Proverbs
stringlengths
8
373
Labels
int64
0
1
Bí șòbià yóò bá degbò Olúgànbe làá ké é sí.
1
Ẹ kúulé là ń kárá ilé, ẹ káàbọ̀ là ń kérò ọ̀nà.
0
Àjọ àláàbò mú àwọn agbódegbà ní Orísúnmbáre.
0
·Bi ẹ bá féyin arúgbóó rí, kí e bèèrè okọ e lowo e.
1
Ajániláyà bí àì-lówó-lọ́wọ́, àìlówó baba ìjayà, owó ní ń túniṣe.
1
Ànìkànjẹ ayé kì í dùn; jíjọjẹ ní ńdára.
1
Àjòjì ò r ni jẹ́rìí-i rẹ̀.
1
Ẹni obìnrin rẹ ń bọ, ina l'olúwa rẹ ń ję.
1
A kì í fara sọfà kí a rójú sinkin ẹni.
1
Ọsàn méjì ni mo mu lówùúrọ̀ òní.
0
Fákẹ́yẹ sọ wí pé ọmọ méjì ni òun ti bí.
0
Bọ̀dé Ìgbòho sọ̀rọ̀ lórí ohun tó kan fún ilẹ̀ Yorùbá lọ́dún yìí.
0
Morádékẹ́ sọ pé àwọn ajínigbé tún ń ṣe oògùn owó nínú igbó ọ̀hún.
0
B'ójú Akátá bà léwó, ẹnu adìẹ kọ ló yẹ kí a ti gbọ ọ.
1
A kì í ka igún mọ́ ẹran jíjẹ.
1
Àsẹ-síhìn-ín, àsẹ-sọhùn-ún l'omi koto kì í fi í kún wọnú ilé.
1
Eleyinjúegę lè șài jęleyinjúàánú.
1
A sunkúnrojọ ilé ló ń tú.
1
Wọn yóò ṣe ìtọ́jú tó péye fún ajá náà.
0
Ẹni mọyì obi, ló n jáwé sí i.
1
Etí yẹrí, etí kan 'ò yẹrí.
1
Àwọn ilé gbígbé ọlọ́pọ̀-èrò náà lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta.
0
Ó máa ń ṣòro láti gba àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn gbọ́.
0
Adénúgà kì í fò káàkiri orílẹ̀-èdè.
0
Àgbà tí yó tẹ̀ẹ́ , bó fárí tán, a ní ó ku járá ẹnu.
1
Àwọn kúmúyì ti kó lọ sí ilé tuntun tí wọ́n kọ́.
0
Abíọ́lá sọ wí pé ohun ìtìjú ni àwọn àwòrán tí àwọn alátìlẹ́yìn Bọ́lá ń gbé jáde.
0
Eni pé k Ésù kọlé (se ibùgbé) fóun ni ò gbọn. Ęșu alára nilé lán ló n sùn ikorítá!
1
B'ó bá rẹni k'á wí, a kì í gbọndò kí a tún máa fitọ rawọ.
1
Ilé ìwòsàn ìgandò ti ń fún àwọn ènìyàn tó ṣèṣe ní ìtọ́jú pàjáwìrì.
0
Bí ayá bá mojú ọkọ, alárìnnà a yẹsẹ̀.
1
Abániwí kì í báni débe.
1
Aboyún kì í gbọn kílẹ má jẹ lára ẹ.
1
Ojú kan làdá ń ní.
1
Àgógó lgún kì í pagún.
1
Àyè kì í há adìẹ kó má dèé ìdí àba-a rẹ̀.
1
Eni egún gún lowo, gún lęsę; ọrọ rẹ gba ljókòó.
1
Àìlàṣọ-lọrùn-un pÀká tápèérò fún gbogbo Mọríwo àti Mọrẹrẹ.
1
Orílẹ̀-èdè Ìrọ̀rùn ti ń kó àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ̀ kúrò ní ìlú Súnmọ́mi.
0
Bí alákẹdun-ún bá rọ̀, tó fọwọ́ ṣẹ́; agbọ̀n la ó fi kó ọmọ òwè níbẹ̀.
1
Bí alẹ́ bá lẹ́, à fi ọmọ ayò fún ayò.
1
Agada 'ò morí ẹni rọ ọ (rọ òun) mọ.
1
Àjọ iléeṣẹ́ tó ń rí sọ́rọ̀ àwọn obìnrin ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti fi páńpẹ́ òfin gbé Adéwálé.
0
Àwòkó, wọ́n ní o bú ọba; ó ní ìgbà wo lòun ráyè bú ọba, kí òun tó kọ igba láàárọ̀, igba lọ́sànán; igba lálẹ́ ?
1
Àbọ̀ ọ̀rọ̀ là á sọ fún ọmọlúàbí, bó bá dénú ẹ̀ á dodidi.
0
Eleyelé parí òwò.
1
Eégún tí ń bẹ́ ọmọ lórí kì í dẹ́rù ba ọmo-ọ tirẹ̀.
1
Àníyàn ladì fi imú ṣe; adìẹ kì í fọnkun.
1
A kì í bínú atọkùn kí á dìgbò lu eégún.
1
Arákùnrin Aláyọ̀tẹ́tí ti ń bá àbúrò mi sùn láti ọjọ́ pípẹ́.
0
B'ẹlẹdẹ bá pààfọ tán, a máa wá ẹni rere tí yóò fi yí lára.
1
Èkó jẹ́ olú ìlú fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí.
0
À ì dẹ'sà dópin l'ọmọdé ò mórí-eku délé.
1
À-jẹ-pọ̀ ni tàdán.
1
Bí 'ò sí ť'Oșó, bi 'ò sí ťÀję, ilé-ayé fàájì ni.
1
Àwọn mọ̀lẹ́bí ti lọ gba òkú àwọn méjì yòókù.
0
A kì í yínmú kí a súfèe; a kì í súfèé ká yínmú.
1
Àsúnmọ́ dẹ̀tẹ́ ; òkèèrè ní ń dùn.
1
Èèyaǹ púpọ̀ ló ṣọ ṣẹ̀ṣẹ̀ kó àrùn ní Nàìjíríà.
0
Àlùfáà àgbà ìjọ àgùdà gbàdúrà fún àwọn aboyún.
0
Àwòrò tí a ò bá lù kì í luni.
1
Ayéfẹ́lẹ́ ní ìrètí ńlá pé òjò iwájú yóò dáa.
0
Bí Fúnmiláyọ̀ ti jẹun tán tí ó fẹ́ tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ ni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ gbà á mọ́ ọn lẹ́nu.
0
Bóòótọ ẹnu ẹni bá se mọ, làsẹ ẹnu enií mọ.
1
Ilé iṣẹ́ àgbẹ̀ kan ní Àjàṣẹ́-Ìpó wọ́ àwọn akọ̀ròyìn méjì lọ sí ilé ẹjọ́.
0
Ayé bàjẹ Olorì ń nájà-oko.
1
Ẹ j ká mí, ẹ j ká simi; èèyàn ní ń fìdí èèyàn jókòó; èèyàn ìbá ṣe bí Ọlọ́run kò níí jẹ́ ká mí.
1
Ààrẹ buwọ́lu bílíọ̀nù mẹ́wàá láti dá ibùdó afẹ́fẹ́ gáàsì sílẹ̀.
0
Bá 'ò gbàgbéọrọ àná, a 'ò ní rẹni àbáseré.(
1
"Agbẹyìnkùnlé retí ohùn ló ń ba ara rẹ nínú je."
1
Ọbásanjọ́ ti kọ lẹ́tà pàtàkì kan sí àwọn aláṣẹ ilé ẹjọ́ ilẹ̀ òkèèrè.
0
A kì í gb'ọnà-ẹbùrú wọlé-ìmọ.
1
B'éèyàn bá tọpa odò látọjù, tí 'ò tètè bìreyìn, kò ní sài bÓlúẹrípàdé l'óòruIn gangan.
1
Adébọwálé ti ṣàlàyé pé láti bí ọdún méjì sẹ́yìn ni Àkànbí ti ṣe àṣemáṣe tí wọ́n fẹ̀sùn rẹ̀ kàn án yìí.
0
‘‘Má fẹ̀ẹ́ ọwọ́-ọ̀ mi kù’’ tí ń yan gúgúrú fún eégún; eégún náàá ní ‘‘Má fẹ̀ẹ́ ọwọ́-ọ̀ mi kù’’; ó fún un ní ọmọláńgidi.
1
B'ẹrú pẹ nílé a lóun yóó joyè, bíwọfà bá pẹ; wọn a láwọn ó jọba.
1
Atàkò fọ́ ẹyin àparò: ohun ojú ń wá lojú ńrí.
1
Eré àwọn ayálégbé sọ̀rọ̀ nípa àwọn apànìyàn.
0
Ẹni tí kò ì kú, kò ì mọ irú ikú tí yóó pàun.
1
Apá ọmọdé ò ká oyè-e bàrà.
1
Ọkọ̀ àjàgbé kan ń bá eré burúkú bọ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ọ̀nà márosẹ̀ tó lọ sí Sángo.
0
Eégún níí ș'ẹnujẹjẹ mutí. Òòșà níí jẹnu wọmù jobì.
1
A rí èèmọ̀ lÉréko; ajá wẹ̀wù ó róṣọ.
1
Àwọn ajínigbé sọ fún Ayọ̀mídé pé àwọn yóò yin ìbọn pa á bí kò bá tẹ̀lé àwọn.
0
Àtúpalẹ̀ ìlànà bí wọ́n ṣe kojú ìwà ìbàjẹ́ nínú ìwé ìtàn àròsọ náà.
0
Èdè aìyedè wà lórí bí ẹ̀gbọ́n ìyàwó Bukola ṣe kú ní Èkó.
0
Àwọ́n ènìyàn máa ń sọ ìdí wùkẹ̀ sí àwọn orin Àyìndé.
0
Wọ́n kó àwọn ẹni afurasí lọ ilé ẹjọ́.
0
À-fi-ọ̀rọ̀-wé-ọ̀rọ̀ ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tán bọ̀rọ̀.
1
Ọ̀gá ọlọ́pàá ní kí wọ́n bá àwọn adigunjalè ṣe ẹjọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti wá wọn rí.
0
A-ká-ìgbá-tà-á náwó ikú.
1
Dì ẹ́ǹdì lòpin-in sinimá.
1
Bàbá Ayọ̀míkún bú sẹ̀kún lẹ́yìn tí àyẹ̀wò kùnà láti sọ ikú tí ó pa ọmọ rẹ̀.
0
Abọ́sẹ̀dé Àyìnlá tíí ṣe olùkéde fún àjọ tó ń rí sí ìlera ló sọ èyí
0
‘‘Mo mọ̀wọ̀n ara-à mi’’ kì í ṣẹ̀rẹ̀kẹ́ èébú.
1
Baálé àìlọ́wọ̀ ni àlejò àìlọ́wọ̀.
1
Àwọn ará ìlú ti lọ fi ìfẹ̀hónú wọn hàn lọ́dọ̀ àwọn olóyè ìlú.
0
Hòo bìl' n 'ò ní bùn o jẹ', 'Mo yó',タ findairúuwon lára (lágara).
1
Mi ò rò pé ìjà tí wọ́n jà lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ló ṣokùnfà ikú rẹ̀.
0
Asọyàyà tó bá dáràn egbàá tó mú u jẹ, òsónú, owó ńlánlá ni yóò fi san.
1