labels
class label 5
classes | headline
stringlengths 38
163
| text
stringlengths 74
42.6k
| headline_text
stringlengths 142
42.7k
| url
stringlengths 35
53
|
---|---|---|---|---|
2health
| Tí ìgbẹ́ tóò ń yà bá rí báyìí? Àìsàn jẹjẹrẹ ikùn ló dé o! Wo bí wàá ṣe dàa mọ̀ | Ìlera ní Yorùbá pè ní oògùn ọrọ̀, àláfíà ẹni kọ̀ọ̀kan wa kò sì ní di fíafìa. Onírúurú àìsàn ló wà lóde òní tó jẹ́ wí pé àìní àkíyèsí àwọn ènìyàn tó ló jẹ́ kí ẹlòmíràn bá àìsàn náà lọ. Lára àwọn àìsàn tí àwọn ènìyàn kò le tètè kọbi ara sí ni àìsàn jẹjẹrẹ inú ikún nítorí àwọn nǹkan tó rọ̀ mọ. Àìsàn jẹjẹrẹ ikùn ni jẹjẹrẹ tó máa ń mú ènìyàn nínú ìfun. Òhun ni àwọn olóyìnbó ń pè ní Bowel cancer tàbí Colon/Rectal cancer. Dame Deborah James, tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ jẹjẹrẹ ikùn lẹ́ni ogójì ọdún ní UK rọ àwọn ènìyàn ṣaájú kó tó kú láti máa yẹ ìgbẹ́ wọn wò nígbàkúgbà tí wọ́n bá ti ya ìgbẹ́. Àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta ló ṣe pàtàkì jùlọ láti mọ̀ bóyá ènìyàn ní àìsàn jẹjẹrẹ ikùn. Kò túmọ̀ sí pé tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣe ènìyàn onítọ̀hún ti ní àìsàn jẹjẹrẹ ikún àmọ́ ó ṣe pàtàkì fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti lọ rí àwọn dókítà fún àyẹ̀wò tó péye pàápàá tó bá ti lé ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí àwọn àpẹẹrẹ yìí bá ti ń wà lára. Àwọn nǹkan náà nìyí: Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn ni Gẹ́gẹ́ bí àwọn àìsàn jẹjẹrẹ yòókù, tí ènìyàn bá tètè mọ̀ wí pé ó wà lára, ó ṣeéṣe kí ènìyàn rí ìtọ́jú tó péye gbà lórí àìsàn náà. Bákan náà ni àìsàn jẹjẹrẹ ikùn lé ṣokùnfà kí ènìyàn má rì í ìgbẹ́ yà, tó sì lè dá àárẹ̀ sára ènìyàn. Lára ohun tí ó dára kí ènìyàn máa ṣe ni yíyẹ ìgbẹ́ ènìyàn tí ènìyàn bá ti ya ìgbẹ́ tán láti mọ bí ó ṣe rí nítorí bí ìgbẹ́ ènìyàn bá ṣe rí jẹ́ ọ̀nà láti fi mọ ìlera ènìyàn. Wò bóyá kò sí ẹ̀jẹ̀ nínú ìgbẹ́ rẹ tàbí ní ìdí rẹ. Ìgbà mìíràn tó jẹ́ wí pé jẹ̀dí ló máa ń fa kí ẹ̀jẹ̀ wà nínú ìgbẹ́ ènìyàn àmọ́ àìsàn jẹjẹrẹ ikùn náà máa ń fà á. Kò ì tíì sí ìwádìí kankan tó fi ohun tó ń fa àìsàn jẹjẹrẹ ikùn múlẹ̀ àmọ́ àwọn nǹkan wà tó le mú kí àìsàn yìí tètè dàgbà lára. Gẹ́gẹ́ bí ibi tí ìwádìí mọ báyìí, àìsàn jẹjẹrẹ kò le ràn láti ìyá tàbí bàbá sọ́mọ àmọ́ ó ṣe pàtàkì kí ẹni tí wọ́n bá ti ní àìsàn yìí ní ìran rẹ̀ fi tó àwọn dókítà létí. Bákan náà ẹni tó bá ní àìsàn Lynch syndrome ṣeéṣe kó ní àìsàn jẹjẹrẹ ikùn ṣùgbọ́n ó ṣe é mójútó tí àwọn dókítà bá tètè mọ̀. Bákan náà tí ènìyàn bá ń gbé ìgbé ayé àláfíà, tó ń jẹ àwọn oúnjẹ tó le ṣe ara ní àǹfàní le mórí bọ́ lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ. Colonoscopy jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n máa ń fi ẹ̀rọ ayàwòrán wo inú ènìyàn láti mọ irú nǹkan tó wà níbẹ̀. Wọ́n le fi ẹ̀rọ yìí mọ̀ tí ènìyǹ bá ní àìsàn jẹjẹrẹ ikùn. Àìsàn jẹjẹrẹ ṣe é tọ́jú tí wọ́n bá tètè ṣàwárí rẹ̀ nígbà tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Ìdá àádọ́sàn-án ènìyàn tí wọ́n bá tètè mọ̀ wí pé ó ní àìsàn ló ní àǹfàní láti lo ọdún márùn-ún sí láyé nígbà kan àmọ́ wọ́n ní ẹni náà le lo ọdún mẹ́wàá sí báyìí. Kò sí ìpele tí àìsàn náà bá wà tí kò sí ìtọ́jú fún gẹ̀gẹ̀ bí àwọn onímọ̀ ṣe ṣọ. Ìpele mẹ́rin ni àìsàn jẹjẹrẹ máa ń wà A lérò wí pé ẹ ti di ohun kan tàbí òmíràn mú, tí ẹ ó sì mú ìlera ara yín ní ọ̀kúnkúndùn, ẹ ò ní máa sáré dìde kúrò ní yàrá ìgbọ̀nsẹ̀ tí ẹ bá ti yàgbẹ́ tán. Yẹ ìgbẹ́ rẹ wò kí o tó kúrò nílé ìgbọ̀nsẹ̀ fún ìlera ara rẹ. | Tí ìgbẹ́ tóò ń yà bá rí báyìí? Àìsàn jẹjẹrẹ ikùn ló dé o! Wo bí wàá ṣe dàa mọ̀ Ìlera ní Yorùbá pè ní oògùn ọrọ̀, àláfíà ẹni kọ̀ọ̀kan wa kò sì ní di fíafìa. Onírúurú àìsàn ló wà lóde òní tó jẹ́ wí pé àìní àkíyèsí àwọn ènìyàn tó ló jẹ́ kí ẹlòmíràn bá àìsàn náà lọ. Lára àwọn àìsàn tí àwọn ènìyàn kò le tètè kọbi ara sí ni àìsàn jẹjẹrẹ inú ikún nítorí àwọn nǹkan tó rọ̀ mọ. Àìsàn jẹjẹrẹ ikùn ni jẹjẹrẹ tó máa ń mú ènìyàn nínú ìfun. Òhun ni àwọn olóyìnbó ń pè ní Bowel cancer tàbí Colon/Rectal cancer. Dame Deborah James, tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ jẹjẹrẹ ikùn lẹ́ni ogójì ọdún ní UK rọ àwọn ènìyàn ṣaájú kó tó kú láti máa yẹ ìgbẹ́ wọn wò nígbàkúgbà tí wọ́n bá ti ya ìgbẹ́. Àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta ló ṣe pàtàkì jùlọ láti mọ̀ bóyá ènìyàn ní àìsàn jẹjẹrẹ ikùn. Kò túmọ̀ sí pé tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣe ènìyàn onítọ̀hún ti ní àìsàn jẹjẹrẹ ikún àmọ́ ó ṣe pàtàkì fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti lọ rí àwọn dókítà fún àyẹ̀wò tó péye pàápàá tó bá ti lé ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí àwọn àpẹẹrẹ yìí bá ti ń wà lára. Àwọn nǹkan náà nìyí: Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn ni Gẹ́gẹ́ bí àwọn àìsàn jẹjẹrẹ yòókù, tí ènìyàn bá tètè mọ̀ wí pé ó wà lára, ó ṣeéṣe kí ènìyàn rí ìtọ́jú tó péye gbà lórí àìsàn náà. Bákan náà ni àìsàn jẹjẹrẹ ikùn lé ṣokùnfà kí ènìyàn má rì í ìgbẹ́ yà, tó sì lè dá àárẹ̀ sára ènìyàn. Lára ohun tí ó dára kí ènìyàn máa ṣe ni yíyẹ ìgbẹ́ ènìyàn tí ènìyàn bá ti ya ìgbẹ́ tán láti mọ bí ó ṣe rí nítorí bí ìgbẹ́ ènìyàn bá ṣe rí jẹ́ ọ̀nà láti fi mọ ìlera ènìyàn. Wò bóyá kò sí ẹ̀jẹ̀ nínú ìgbẹ́ rẹ tàbí ní ìdí rẹ. Ìgbà mìíràn tó jẹ́ wí pé jẹ̀dí ló máa ń fa kí ẹ̀jẹ̀ wà nínú ìgbẹ́ ènìyàn àmọ́ àìsàn jẹjẹrẹ ikùn náà máa ń fà á. Kò ì tíì sí ìwádìí kankan tó fi ohun tó ń fa àìsàn jẹjẹrẹ ikùn múlẹ̀ àmọ́ àwọn nǹkan wà tó le mú kí àìsàn yìí tètè dàgbà lára. Gẹ́gẹ́ bí ibi tí ìwádìí mọ báyìí, àìsàn jẹjẹrẹ kò le ràn láti ìyá tàbí bàbá sọ́mọ àmọ́ ó ṣe pàtàkì kí ẹni tí wọ́n bá ti ní àìsàn yìí ní ìran rẹ̀ fi tó àwọn dókítà létí. Bákan náà ẹni tó bá ní àìsàn Lynch syndrome ṣeéṣe kó ní àìsàn jẹjẹrẹ ikùn ṣùgbọ́n ó ṣe é mójútó tí àwọn dókítà bá tètè mọ̀. Bákan náà tí ènìyàn bá ń gbé ìgbé ayé àláfíà, tó ń jẹ àwọn oúnjẹ tó le ṣe ara ní àǹfàní le mórí bọ́ lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ. Colonoscopy jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n máa ń fi ẹ̀rọ ayàwòrán wo inú ènìyàn láti mọ irú nǹkan tó wà níbẹ̀. Wọ́n le fi ẹ̀rọ yìí mọ̀ tí ènìyǹ bá ní àìsàn jẹjẹrẹ ikùn. Àìsàn jẹjẹrẹ ṣe é tọ́jú tí wọ́n bá tètè ṣàwárí rẹ̀ nígbà tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Ìdá àádọ́sàn-án ènìyàn tí wọ́n bá tètè mọ̀ wí pé ó ní àìsàn ló ní àǹfàní láti lo ọdún márùn-ún sí láyé nígbà kan àmọ́ wọ́n ní ẹni náà le lo ọdún mẹ́wàá sí báyìí. Kò sí ìpele tí àìsàn náà bá wà tí kò sí ìtọ́jú fún gẹ̀gẹ̀ bí àwọn onímọ̀ ṣe ṣọ. Ìpele mẹ́rin ni àìsàn jẹjẹrẹ máa ń wà A lérò wí pé ẹ ti di ohun kan tàbí òmíràn mú, tí ẹ ó sì mú ìlera ara yín ní ọ̀kúnkúndùn, ẹ ò ní máa sáré dìde kúrò ní yàrá ìgbọ̀nsẹ̀ tí ẹ bá ti yàgbẹ́ tán. Yẹ ìgbẹ́ rẹ wò kí o tó kúrò nílé ìgbọ̀nsẹ̀ fún ìlera ara rẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/c0w5qxr417zo |
2health
| Breastfeeding: Wo àwọn oúnjẹ́ tí yóò mú kí omi ọmú pọ̀ si fún ìyálọ́mọ́ | Ọpọlọpọ ounjẹ lo wa, to le ṣe awọn iyalọmọ to n fun ọmọ ni ọyan ni anfaani, ki omi ọmu wọn le pọ si. Iru ounjẹ ti obinrin to n tọ ikoko lọwọ ba jẹ, ni yoo sọ bi ilera oun ati ọmọ rẹ yoo se ri. Ṣugbọn ṣa, ọpọlọpọ obinrin lo maa n jẹ oriṣiriṣi 'ijẹkujẹ', lasiko ti wọn ba n fun ọmọ ni ọmu, nitori pe wọn ko mọ nipa iru ounjẹ ti wọn le ma a jẹ. BBC ba onimọ nipa ounjẹ, Florence Uchendu ati onimọ nipa bi obinrin ṣe n fun ọmọ ni ọmu, Maryam Sanuth sọrọ, lati ṣalaye iru ounjẹ ti obinrin le ma a jẹ, ki omi ọmu rẹ le pọ si. Gẹgẹ bi Arabinrin Sanuth Maryam ṣe sọ, ti oyun obinrin ba ti pe ogún ọsẹ, ni ọmu rẹ yoo ti ma a ni omi. O ṣalaye pe lasiko yii ni obinrin yoo ṣakiyesi pe ọmu oun n tobi si i. Ni kete ti obinrin naa ba si bimọ tan, eroja ara ti wọn n pe ni prolactin ati oxytocin yoo bẹrẹ si ni jade sinu ọmu. Awọn ounjẹ to le mu ki omi ọmu pọ si: Florence Uchendu sọ pe, o ṣe pataki fun obinrin to sẹṣẹ bimọ lati ma a jẹ awọn nkan wọnyii, nitori pe o ni ipa pataki fun ipese omi ọmu. O ni wọn tun ma n mu ki awọn ẹjẹ to di sinu ile ọmọ, tete ṣan jade kuro ninu ara. Yatọ si eyi, o tun sọ pe yoo jẹ ki ọmu obinrin duro daadaa. Arabinrin Sanuth sọ pe mimu ẹkọ gbigbona naa ṣe koko fun ipese omi ọyan. Uchendu paapaa fikun pe, lootọ ni ẹkọ mimu dara fun obinrin to n fun ọmọ ni ọmu, amọ o dara ko mu ẹkọ naa pẹlu miliki lai ni ṣuga, to le koba ọmọ tuntun. O ni eroja aṣara loore protein to wa ninu miliki ṣe pataki fun awọn obinrin to n fun ọmọ ni ọyan. Ata ilẹ ati alubọsa ayu (Ginger ati Garlic) Arabinrin Maryam Sanuth sọ pe galiiki ni anfaani pupọ, paapaa fun awọn obinrin to n fun ọmọ ni ọyan. O ni wọn tun le fi sinu omi ti ko gbona ju, fun mimu. Sanuth sọ pe eroja aṣaraloore Fiber ati ọpọlọpọ eroja mii lo wa ninu oat, eyi to mu ko dara fun iyalọmọ ni jijẹ ni gbogbo igba. Bakan naa lo tun ni awọn ounjẹ onikoro bi imumu ati ẹpa naa dara. Imumu, ti wọn n pe ni tigernut ni ede Gẹẹsi, ni wọn fi n ṣe Kunnu Aya. O ni ti obinrin ba n mu bi ẹẹmẹta lojumọ, yoo mu ki omi pọ daadaa ni ọmu rẹ, o O ni iyalọmọ le ma a mu ṣibi ewe moringa ti wọn gun lojoojumọ. Florence Uchendu sọ pe o ṣe koko fun obinrin to n fun ọmọ ni ọmu lati ma a jẹun daadaa, nitori pe yoo tete ma a rẹ ẹ. Fun awọn obinrin to ni aisan itọ ṣuga, Uchendu sọ pe bi wọn ṣe n jẹun tẹlẹ ki wọn o to bimọ, naa ni ki wọn o tẹsiwaju. O ni o le jẹ ọgẹdẹ dodo ti ko pọn, tabi iṣu sise. | Breastfeeding: Wo àwọn oúnjẹ́ tí yóò mú kí omi ọmú pọ̀ si fún ìyálọ́mọ́ Ọpọlọpọ ounjẹ lo wa, to le ṣe awọn iyalọmọ to n fun ọmọ ni ọyan ni anfaani, ki omi ọmu wọn le pọ si. Iru ounjẹ ti obinrin to n tọ ikoko lọwọ ba jẹ, ni yoo sọ bi ilera oun ati ọmọ rẹ yoo se ri. Ṣugbọn ṣa, ọpọlọpọ obinrin lo maa n jẹ oriṣiriṣi 'ijẹkujẹ', lasiko ti wọn ba n fun ọmọ ni ọmu, nitori pe wọn ko mọ nipa iru ounjẹ ti wọn le ma a jẹ. BBC ba onimọ nipa ounjẹ, Florence Uchendu ati onimọ nipa bi obinrin ṣe n fun ọmọ ni ọmu, Maryam Sanuth sọrọ, lati ṣalaye iru ounjẹ ti obinrin le ma a jẹ, ki omi ọmu rẹ le pọ si. Gẹgẹ bi Arabinrin Sanuth Maryam ṣe sọ, ti oyun obinrin ba ti pe ogún ọsẹ, ni ọmu rẹ yoo ti ma a ni omi. O ṣalaye pe lasiko yii ni obinrin yoo ṣakiyesi pe ọmu oun n tobi si i. Ni kete ti obinrin naa ba si bimọ tan, eroja ara ti wọn n pe ni prolactin ati oxytocin yoo bẹrẹ si ni jade sinu ọmu. Awọn ounjẹ to le mu ki omi ọmu pọ si: Florence Uchendu sọ pe, o ṣe pataki fun obinrin to sẹṣẹ bimọ lati ma a jẹ awọn nkan wọnyii, nitori pe o ni ipa pataki fun ipese omi ọmu. O ni wọn tun ma n mu ki awọn ẹjẹ to di sinu ile ọmọ, tete ṣan jade kuro ninu ara. Yatọ si eyi, o tun sọ pe yoo jẹ ki ọmu obinrin duro daadaa. Arabinrin Sanuth sọ pe mimu ẹkọ gbigbona naa ṣe koko fun ipese omi ọyan. Uchendu paapaa fikun pe, lootọ ni ẹkọ mimu dara fun obinrin to n fun ọmọ ni ọmu, amọ o dara ko mu ẹkọ naa pẹlu miliki lai ni ṣuga, to le koba ọmọ tuntun. O ni eroja aṣara loore protein to wa ninu miliki ṣe pataki fun awọn obinrin to n fun ọmọ ni ọyan. Ata ilẹ ati alubọsa ayu (Ginger ati Garlic) Arabinrin Maryam Sanuth sọ pe galiiki ni anfaani pupọ, paapaa fun awọn obinrin to n fun ọmọ ni ọyan. O ni wọn tun le fi sinu omi ti ko gbona ju, fun mimu. Sanuth sọ pe eroja aṣaraloore Fiber ati ọpọlọpọ eroja mii lo wa ninu oat, eyi to mu ko dara fun iyalọmọ ni jijẹ ni gbogbo igba. Bakan naa lo tun ni awọn ounjẹ onikoro bi imumu ati ẹpa naa dara. Imumu, ti wọn n pe ni tigernut ni ede Gẹẹsi, ni wọn fi n ṣe Kunnu Aya. O ni ti obinrin ba n mu bi ẹẹmẹta lojumọ, yoo mu ki omi pọ daadaa ni ọmu rẹ, o O ni iyalọmọ le ma a mu ṣibi ewe moringa ti wọn gun lojoojumọ. Florence Uchendu sọ pe o ṣe koko fun obinrin to n fun ọmọ ni ọmu lati ma a jẹun daadaa, nitori pe yoo tete ma a rẹ ẹ. Fun awọn obinrin to ni aisan itọ ṣuga, Uchendu sọ pe bi wọn ṣe n jẹun tẹlẹ ki wọn o to bimọ, naa ni ki wọn o tẹsiwaju. O ni o le jẹ ọgẹdẹ dodo ti ko pọn, tabi iṣu sise. | https://www.bbc.com/yoruba/awon-iroyin-miran-55609159 |
4religion
| Pastor Adeboye: Ìyàwó Adeboye ní ó jẹ́ okùnrin tí gbogbo obìnrin fẹ́ràn láti fi ṣe ọkọ | Iyawo pasitọ Enoch Adeboye, Foluke Adeboye ti sapajuwe ọkọ rẹ gẹgẹ bi ọkunrin akinkanju ti gbogbo obinrin fẹran lati fi ṣe ọkọ. Foluke Adeboye sọ bẹẹ ni oju ọpọ ikansiraẹni Twitter rẹ lasiko ti wọn ṣe ayẹyẹ pasitọ Adeboye to pe ẹni ọdun mọkandinlọgọrin. Pasitọ Adeboye ni adari ijọ irapada, The Redeemed Christian Church of God kaakiri gbogbo agbayẹ. Pasitọ Foluke ni Ọlọrun nigba to n ṣẹda Enoch Adeboye ni nkan bi ọdun mọkandinlọgọrin ṣẹyin ṣe ẹda rẹ fun oun Foluke gẹgẹ bi ade ori. O ni Ọlọrun mọ wi pe oun nilọ akinkanju ọkunrin, ọba, alufaa, woli ati ọkunrin to nirẹlẹ to ṣe e mu yangan, ti pasitọ Adeboye jẹ. ''Adeboye, O da mi loju wi pe Ọlọrun da ẹ fun mi ni o'' ''Mo dupẹ lọwọ rẹ fun ifẹ to fihan mi, emi naa si fẹran rẹ tọkantọkan.'' ''Iwọ ni ọkunrin naa ti gbogbo obinrin fẹ fi ṣe ọkọ wọn, ti gbogbo ọmọ fẹ ko jẹ baba wọn'' Iyawo Adeboye gbadura fun ọkọ rẹ pe ki Ọlọrun da ẹmi rẹ si , ko si ṣe ọpọlọpọ ọdun laye. Bakan naa lo gbadura wi pe ki ilera ati ọrọ kun igbeaye pasitọ Adeboye, ki awọn si gbepọ ni irẹpọ titi opin aye wọn. Ọjọ Keji, Oṣu Kẹta ni Pasitọ Adeboye to jẹ adari ijọ irapada, The Redeemed Christian Church of God pe ẹni ọdun mọkandinlọgọrin. | Pastor Adeboye: Ìyàwó Adeboye ní ó jẹ́ okùnrin tí gbogbo obìnrin fẹ́ràn láti fi ṣe ọkọ Iyawo pasitọ Enoch Adeboye, Foluke Adeboye ti sapajuwe ọkọ rẹ gẹgẹ bi ọkunrin akinkanju ti gbogbo obinrin fẹran lati fi ṣe ọkọ. Foluke Adeboye sọ bẹẹ ni oju ọpọ ikansiraẹni Twitter rẹ lasiko ti wọn ṣe ayẹyẹ pasitọ Adeboye to pe ẹni ọdun mọkandinlọgọrin. Pasitọ Adeboye ni adari ijọ irapada, The Redeemed Christian Church of God kaakiri gbogbo agbayẹ. Pasitọ Foluke ni Ọlọrun nigba to n ṣẹda Enoch Adeboye ni nkan bi ọdun mọkandinlọgọrin ṣẹyin ṣe ẹda rẹ fun oun Foluke gẹgẹ bi ade ori. O ni Ọlọrun mọ wi pe oun nilọ akinkanju ọkunrin, ọba, alufaa, woli ati ọkunrin to nirẹlẹ to ṣe e mu yangan, ti pasitọ Adeboye jẹ. ''Adeboye, O da mi loju wi pe Ọlọrun da ẹ fun mi ni o'' ''Mo dupẹ lọwọ rẹ fun ifẹ to fihan mi, emi naa si fẹran rẹ tọkantọkan.'' ''Iwọ ni ọkunrin naa ti gbogbo obinrin fẹ fi ṣe ọkọ wọn, ti gbogbo ọmọ fẹ ko jẹ baba wọn'' Iyawo Adeboye gbadura fun ọkọ rẹ pe ki Ọlọrun da ẹmi rẹ si , ko si ṣe ọpọlọpọ ọdun laye. Bakan naa lo gbadura wi pe ki ilera ati ọrọ kun igbeaye pasitọ Adeboye, ki awọn si gbepọ ni irẹpọ titi opin aye wọn. Ọjọ Keji, Oṣu Kẹta ni Pasitọ Adeboye to jẹ adari ijọ irapada, The Redeemed Christian Church of God pe ẹni ọdun mọkandinlọgọrin. | https://www.bbc.com/yoruba/56262187 |
2health
| Charles Olumo Agbako ń ṣe àìsàn ńlá, ó ní ara ń ni òun | Òdú ni gbajúgbajà òṣèré tíátà nnì, Abdulsalam Ishola ẹni tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Charles Olúmọ Àgbákò lagbo tiata. Láàárín ọdún 1990 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000, àwọn ipa líle tí Charles Olúmọ Àgbákò máa ń kó nínú eré jẹ́ kó di ìlú mọ̀ọ́kà láàárín àwọn àgbà òṣèré. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, gbajúmọ̀ òṣèré yìí gba ikọ̀ BBC Yorùbá ní àlejò, tí baba naa sì ṣàlàyé bí ìrìnàjò wọn nínú eré sinimá ṣe bẹ̀rẹ̀. Bakan naa lo tun salaye àwọn ipa ribiribi to ti ko sẹyin ninu eré sinimá nínú ìgbésí ayé wọn. Kódà bàbá Charles Olúmọ Àgbákò fi yé wa nígbà náà wí pé, kokoko ni ara ọta oun le. Agbako ni oun ṣì lè ṣeré tíátà ti wọ́n bá pe oun sí iṣẹ́ pẹ̀lú bí ọjọ́ orí oun ṣe ti ń súnmọ́ ọgọ́rùn-ún ọdún lọ. Eyi lo mu ko jẹ ìyàlẹ́nu nla fún BBC Yoruba nígbà tí a gbọ́ wí pé bàbá tó ń fò sókè ní bi oṣù mélòó kan sẹ́yìn ni òjòjò ń ṣe Ògún rẹ̀ báyìí. Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí ilé bàbá Charles Olúmọ Àgbákò láti mọ ipò ìlera tí bàbá náà wà, àgbà òṣèré náà ṣàlàyé bí àárẹ̀ tó ń ba jà ṣe bẹ̀rẹ̀ ní bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn. Àgbákò ṣàlàyé pé ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni òun ṣàdédé ri wí pé òun kò le yàgbẹ́ tàbí tọ̀ ní ìrọ̀rùn. Ó ní èyí ló mú kí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ òun gbé òun lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú, tí àwọn dókítà sì ní iṣẹ́ abẹ ló le tán ìṣòro ohun tó ń bá òun fínra lọ́dún náà. Ó fi kun pé, lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ náà tán, ni ojú ọgbẹ́ ibi tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ ọ̀hún máa ń da òun láàmú tí òun sì tún padà lọ sí ilé ìwòsàn náà. "Nígbà tí mo padà lọ sí ilé ìwòsàn, wọ́n fún mi ní àwọn òògùn àti nǹkan mìíràn láti máa lò láti fi tọ́jú ibi ojú ọgbẹ́ náà" Charles Olúmọ Àgbákò tẹ̀síwájú pé, lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni òun tún ń ri pé àti yàgbẹ́ àti tọ̀, tún bẹ̀rẹ̀ sí ní di ìjọ̀gbọ̀n. Ó ní dókítà ní ó jẹ́ kí ó yé òun wí pé, iṣẹ́ abẹ ọjọ́ kìíní kò jìnà wọnú èyí ló sì fa àìlera gbogbo ìgbà tó ń bá òun fínra báyìí. Bákan náà ló ní wọ́n jẹ́ kó yé òun wí pé ìfun òun ti já sínú ẹpọ̀n òun tí àwọn sì nílò láti ko kúrò níbẹ̀, ko le bọ́ sí àyè tó yẹ kó wà gangan nínú ikùn. Ó ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn dókítà ní òun kò le ṣe iṣẹ́ abẹ bíi ti ìgbà àkọ́kọ́ mọ́, àwọn ìgbésẹ̀ wà tí wọn yóò gbé láti mú kí ìfun náà padà sí ààyè rẹ̀, kí ìnira tí ó ń kó bá òun náà dínkù jọjọ. "Nígbà tí mo dé ilé ìwòsàn, dókítà ní mi ò le ṣe iṣẹ́ abẹ mọ́, wọ́n ní ki n ṣáà ma lọ lo oògùn, gbogbo ògùn tí wọ́n ń kọ fún mi ni mò ń rà, tí àwọn ènìyàn mi dẹ̀ ń rà fún mi." Àgbákò ní lóòótọ́ ni àwọn ògùn tí àwọn dókítà kọ fún òun ń ṣiṣẹ́ àmọ́ ọjọ́ mẹ́ta mẹ́ta ni òun gba abẹ́rẹ́. O ni awọn abẹrẹ yii lo wa láti fi mú àdínkù bá ìnira tí àìlera ọhun ń kó bá òun. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó ni àwọn ń run sórí àwọn ògùn àti abẹ́rẹ́ yìí, tó sì jẹ́ wí pé kò sí òkun àti ìlera pípé fún òun láti lọ sí oko eré sinimá mọ́. Agbako ni ọ̀wọ́ nǹkan tí àwọn ènìyàn fi ń ran òun lọ́wọ́ nikan lo ku, ti oun n jẹ. Ìyàwó ọmọ Charles Olúmọ Àgbákò, Olamide tó ń tọ́jú bàbá ṣàlàyé fún BBC News Yorùbá pé láti nǹkan bí oṣù mẹ́fà sẹ́yìn, tí ara bàbá kò ti yá, ni òun ti wà pẹ̀lú wọn. Olamide ní ó jẹ́ ohun tó máa ń ba òun àti àwọn ọmọ bàbá lọ́kàn jẹ́ nígbà tí bàbá bá ń tọrọ ikú fún ara wọn nítorí bí ara ṣe ń ni wọn. Ó ní lóòótọ́ ni pé bàbá Àgbákò ti dàgbà, àmọ́ àwọn ò mọ iye ọdún tí Ọlọ́run kọ fún wọn nítorí náà kò ní wù wá kí wọ́n lo ìgbésí ayé wọn tó kù nínú ìnira. Ó fi kun pé ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà ni bàbá Àgbákò nílò lásìkò láti fi bọ́ lọ́wọ́ ìnira tí bàbá náà ń kojú lásìkò yìí. | Charles Olumo Agbako ń ṣe àìsàn ńlá, ó ní ara ń ni òun Òdú ni gbajúgbajà òṣèré tíátà nnì, Abdulsalam Ishola ẹni tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Charles Olúmọ Àgbákò lagbo tiata. Láàárín ọdún 1990 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000, àwọn ipa líle tí Charles Olúmọ Àgbákò máa ń kó nínú eré jẹ́ kó di ìlú mọ̀ọ́kà láàárín àwọn àgbà òṣèré. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, gbajúmọ̀ òṣèré yìí gba ikọ̀ BBC Yorùbá ní àlejò, tí baba naa sì ṣàlàyé bí ìrìnàjò wọn nínú eré sinimá ṣe bẹ̀rẹ̀. Bakan naa lo tun salaye àwọn ipa ribiribi to ti ko sẹyin ninu eré sinimá nínú ìgbésí ayé wọn. Kódà bàbá Charles Olúmọ Àgbákò fi yé wa nígbà náà wí pé, kokoko ni ara ọta oun le. Agbako ni oun ṣì lè ṣeré tíátà ti wọ́n bá pe oun sí iṣẹ́ pẹ̀lú bí ọjọ́ orí oun ṣe ti ń súnmọ́ ọgọ́rùn-ún ọdún lọ. Eyi lo mu ko jẹ ìyàlẹ́nu nla fún BBC Yoruba nígbà tí a gbọ́ wí pé bàbá tó ń fò sókè ní bi oṣù mélòó kan sẹ́yìn ni òjòjò ń ṣe Ògún rẹ̀ báyìí. Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí ilé bàbá Charles Olúmọ Àgbákò láti mọ ipò ìlera tí bàbá náà wà, àgbà òṣèré náà ṣàlàyé bí àárẹ̀ tó ń ba jà ṣe bẹ̀rẹ̀ ní bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn. Àgbákò ṣàlàyé pé ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni òun ṣàdédé ri wí pé òun kò le yàgbẹ́ tàbí tọ̀ ní ìrọ̀rùn. Ó ní èyí ló mú kí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ òun gbé òun lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú, tí àwọn dókítà sì ní iṣẹ́ abẹ ló le tán ìṣòro ohun tó ń bá òun fínra lọ́dún náà. Ó fi kun pé, lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ náà tán, ni ojú ọgbẹ́ ibi tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ ọ̀hún máa ń da òun láàmú tí òun sì tún padà lọ sí ilé ìwòsàn náà. "Nígbà tí mo padà lọ sí ilé ìwòsàn, wọ́n fún mi ní àwọn òògùn àti nǹkan mìíràn láti máa lò láti fi tọ́jú ibi ojú ọgbẹ́ náà" Charles Olúmọ Àgbákò tẹ̀síwájú pé, lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni òun tún ń ri pé àti yàgbẹ́ àti tọ̀, tún bẹ̀rẹ̀ sí ní di ìjọ̀gbọ̀n. Ó ní dókítà ní ó jẹ́ kí ó yé òun wí pé, iṣẹ́ abẹ ọjọ́ kìíní kò jìnà wọnú èyí ló sì fa àìlera gbogbo ìgbà tó ń bá òun fínra báyìí. Bákan náà ló ní wọ́n jẹ́ kó yé òun wí pé ìfun òun ti já sínú ẹpọ̀n òun tí àwọn sì nílò láti ko kúrò níbẹ̀, ko le bọ́ sí àyè tó yẹ kó wà gangan nínú ikùn. Ó ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn dókítà ní òun kò le ṣe iṣẹ́ abẹ bíi ti ìgbà àkọ́kọ́ mọ́, àwọn ìgbésẹ̀ wà tí wọn yóò gbé láti mú kí ìfun náà padà sí ààyè rẹ̀, kí ìnira tí ó ń kó bá òun náà dínkù jọjọ. "Nígbà tí mo dé ilé ìwòsàn, dókítà ní mi ò le ṣe iṣẹ́ abẹ mọ́, wọ́n ní ki n ṣáà ma lọ lo oògùn, gbogbo ògùn tí wọ́n ń kọ fún mi ni mò ń rà, tí àwọn ènìyàn mi dẹ̀ ń rà fún mi." Àgbákò ní lóòótọ́ ni àwọn ògùn tí àwọn dókítà kọ fún òun ń ṣiṣẹ́ àmọ́ ọjọ́ mẹ́ta mẹ́ta ni òun gba abẹ́rẹ́. O ni awọn abẹrẹ yii lo wa láti fi mú àdínkù bá ìnira tí àìlera ọhun ń kó bá òun. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó ni àwọn ń run sórí àwọn ògùn àti abẹ́rẹ́ yìí, tó sì jẹ́ wí pé kò sí òkun àti ìlera pípé fún òun láti lọ sí oko eré sinimá mọ́. Agbako ni ọ̀wọ́ nǹkan tí àwọn ènìyàn fi ń ran òun lọ́wọ́ nikan lo ku, ti oun n jẹ. Ìyàwó ọmọ Charles Olúmọ Àgbákò, Olamide tó ń tọ́jú bàbá ṣàlàyé fún BBC News Yorùbá pé láti nǹkan bí oṣù mẹ́fà sẹ́yìn, tí ara bàbá kò ti yá, ni òun ti wà pẹ̀lú wọn. Olamide ní ó jẹ́ ohun tó máa ń ba òun àti àwọn ọmọ bàbá lọ́kàn jẹ́ nígbà tí bàbá bá ń tọrọ ikú fún ara wọn nítorí bí ara ṣe ń ni wọn. Ó ní lóòótọ́ ni pé bàbá Àgbákò ti dàgbà, àmọ́ àwọn ò mọ iye ọdún tí Ọlọ́run kọ fún wọn nítorí náà kò ní wù wá kí wọ́n lo ìgbésí ayé wọn tó kù nínú ìnira. Ó fi kun pé ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà ni bàbá Àgbákò nílò lásìkò láti fi bọ́ lọ́wọ́ ìnira tí bàbá náà ń kojú lásìkò yìí. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cjrn5w951r4o |
4religion
| US Fake Marriage Pastor: Ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún ni ìkọ̀ọ̀kan ẹ̀sùn jìbìtì àti irọ́ pípa tí wọn fi kan Pásítọ̀ gbérù | Olusọagutan kan ni Maryland lorilẹede Amẹrika, tii se ẹni aadọta ọdun, Joshua Olatokunbo Shonubi ni wọn ti fi ẹsun kan pe o se ọpọ ayederu igbeyawo laarin awọn mẹkunnu nilẹ Amẹrika atawọn ajeji lọna ati gba iwe igbelu. Wọn fi ẹsun kan Pasitọ naa pe o se magomago loju ọna ati gba iwe igbelu ni Amẹrika, to si n se ayederu igbeyawo, ayederu iwe igbelu ati genje iwe adehun gbigba ile. Joshua Olatokunbo Shonubi, to tun n jẹ Olatokunbo Joshua Shonubi, ni awọn agbẹjọro ijọba nilu naa wọ lọ sile ẹjọ pe o n lu jibiti nipa igbeyawo ati iwe asẹ iwọlu taa mọ si Visa, to si tun ko awọn genje iwe ẹri awọn ileesẹ ijọba silẹ. Atẹjade tawọn agbefọba naa fisita ni Shonubi gbe nilu Bowie, to si tun jẹ Pasitọ ijọ New Life City to wa lẹba Hyattsville ni Maryland yii kan naa amọ maili mejila ni ilu mejeeji fi jinna sira wọn. Atẹjade naa ni lati ọdun 2014 titi di ọdun 2021 ni Pasitọ Shonubi fi se magomago yii, to si gba ẹgbẹlẹgbẹ dọla lati ọwọ awọn ajeji ni orilẹede miran pe oun yoo bawọn seto igbeyawo pẹlu awọn ọmọ ilẹ Amẹrika. Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan Shonubi pe gẹgẹ bii Pasitọ, o n gba awọn eeyan ti ko ni agbara lati tọju ara wọn sọdọ rẹ, to si n kọ wọn lati maa se igbeyawo pẹlu awọn ọmọ ilẹ Amẹrika, eyi to ni yoo tete jẹ ki wọn ni iwe igbelu. Nigba mii, Shonubi yii ni wọn lo maa n seto igbeyawo yii funra ara rẹ nile ijọsin rẹ tabi ko ran tọkọ taya naa lọ si Virginia fun ayẹyẹ igbeyawo nla. Awọn agbefọba naa ni ni kete tawọn eeyan naa ba ti se igbeyawo tan, ti wọn si san owo nla fun Shonubi, oun ni yoo ba wọn seto iwe ti wọn yoo fi sọwọ si ileesẹ to n ri si ọrọ iwe igbelu, ti yoo si fi adirẹsi rẹ sibẹ, ọwọ rẹ si ni iwe tabi iroyin nipa igbesẹ naa yoo maa de si. Shonubi yii tun ni wọn ni yoo fi awọn ayederu iwe sọwọ si ileesẹ naa pẹ́lu iwe sọọsi rẹ, ti yoo si sọ nipa bo se mọ tọkọ taya naa si, to si maa n tọ wọn sọna ninu ẹmi ati bi igbeyawo wọn se da lori ifẹ pipe. Wọn ni o to iru ayederu iwe ẹri bayii bii mejidinlogoji ti Shonubi ti se fawọn ofege lọkọ laya, ti yoo si tun pese ẹbu iwe to fihan pe awọn tọkọ tiyawo naa dijọ n gbe papọ ni. Ikọ agbẹjọro agbefọba naa ni Shonubi ni ọwọ ti tẹ bayii, to si ti yọju siwaju adajọ ni Baltimore lọjọ, to si seese ko fi ẹwọn ọdun marun marun jura lori awọn koko ẹsun lilu jibiti ati irọ pipa ti wọn fi kan. | US Fake Marriage Pastor: Ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún ni ìkọ̀ọ̀kan ẹ̀sùn jìbìtì àti irọ́ pípa tí wọn fi kan Pásítọ̀ gbérù Olusọagutan kan ni Maryland lorilẹede Amẹrika, tii se ẹni aadọta ọdun, Joshua Olatokunbo Shonubi ni wọn ti fi ẹsun kan pe o se ọpọ ayederu igbeyawo laarin awọn mẹkunnu nilẹ Amẹrika atawọn ajeji lọna ati gba iwe igbelu. Wọn fi ẹsun kan Pasitọ naa pe o se magomago loju ọna ati gba iwe igbelu ni Amẹrika, to si n se ayederu igbeyawo, ayederu iwe igbelu ati genje iwe adehun gbigba ile. Joshua Olatokunbo Shonubi, to tun n jẹ Olatokunbo Joshua Shonubi, ni awọn agbẹjọro ijọba nilu naa wọ lọ sile ẹjọ pe o n lu jibiti nipa igbeyawo ati iwe asẹ iwọlu taa mọ si Visa, to si tun ko awọn genje iwe ẹri awọn ileesẹ ijọba silẹ. Atẹjade tawọn agbefọba naa fisita ni Shonubi gbe nilu Bowie, to si tun jẹ Pasitọ ijọ New Life City to wa lẹba Hyattsville ni Maryland yii kan naa amọ maili mejila ni ilu mejeeji fi jinna sira wọn. Atẹjade naa ni lati ọdun 2014 titi di ọdun 2021 ni Pasitọ Shonubi fi se magomago yii, to si gba ẹgbẹlẹgbẹ dọla lati ọwọ awọn ajeji ni orilẹede miran pe oun yoo bawọn seto igbeyawo pẹlu awọn ọmọ ilẹ Amẹrika. Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan Shonubi pe gẹgẹ bii Pasitọ, o n gba awọn eeyan ti ko ni agbara lati tọju ara wọn sọdọ rẹ, to si n kọ wọn lati maa se igbeyawo pẹlu awọn ọmọ ilẹ Amẹrika, eyi to ni yoo tete jẹ ki wọn ni iwe igbelu. Nigba mii, Shonubi yii ni wọn lo maa n seto igbeyawo yii funra ara rẹ nile ijọsin rẹ tabi ko ran tọkọ taya naa lọ si Virginia fun ayẹyẹ igbeyawo nla. Awọn agbefọba naa ni ni kete tawọn eeyan naa ba ti se igbeyawo tan, ti wọn si san owo nla fun Shonubi, oun ni yoo ba wọn seto iwe ti wọn yoo fi sọwọ si ileesẹ to n ri si ọrọ iwe igbelu, ti yoo si fi adirẹsi rẹ sibẹ, ọwọ rẹ si ni iwe tabi iroyin nipa igbesẹ naa yoo maa de si. Shonubi yii tun ni wọn ni yoo fi awọn ayederu iwe sọwọ si ileesẹ naa pẹ́lu iwe sọọsi rẹ, ti yoo si sọ nipa bo se mọ tọkọ taya naa si, to si maa n tọ wọn sọna ninu ẹmi ati bi igbeyawo wọn se da lori ifẹ pipe. Wọn ni o to iru ayederu iwe ẹri bayii bii mejidinlogoji ti Shonubi ti se fawọn ofege lọkọ laya, ti yoo si tun pese ẹbu iwe to fihan pe awọn tọkọ tiyawo naa dijọ n gbe papọ ni. Ikọ agbẹjọro agbefọba naa ni Shonubi ni ọwọ ti tẹ bayii, to si ti yọju siwaju adajọ ni Baltimore lọjọ, to si seese ko fi ẹwọn ọdun marun marun jura lori awọn koko ẹsun lilu jibiti ati irọ pipa ti wọn fi kan. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-59033802 |
1entertainment
| Yinka Ayefele: Ìrọ́ ni pé ń kò le ṣe bíi ọkùnrin, mò ń ta pútú dàadáa | Awọn agba ni ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin, bẹẹ si ni bi ẹni ti yoo ba ni ogo, yoo ri ohun sọ nitori inu ẹgbin ni ọla n gbe. Idi ree ti ilumọọka akọrin ẹmi Tungba nni, Ọmọwe Olayinka Joel Ayefele (MON) fi n se alaye ọpọ ohun ti oju rẹ ri, ko to di eeyan lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ. Ayefele, ninu ifọrọwerọ naa, tun salaye bo se bẹrẹ igbesi aye rẹ, awọn isẹ to ti se, ko to ja oju ọna pẹlu bo se ni ijamba ọkọ to da joko sori kẹkẹ lai le rin. Bakan naa ni gbajumọ akọrin ẹmi ati agbohunsafẹfẹ naa tun sọrọ lori oniruuru ahesọ ọrọ tawọn eeyan n gbe kiri nipa oun lati igba ti ijamba ọkọ naa ti waye. Ayefele salaye fun BBC pe ileesẹ redio ijọba apapọ, ta mọ si Radio Nigeria ni oun ti bẹrẹ isẹ ni ibẹrẹ aye oun. O ni isẹ ki oun maa ba wọn gbe baba Keresi lopin ọdun ni oun kọkọ fi bẹrẹ lọdun 1997, ti wọn si n fun oun ni aadọta naira ni ojumọ. O salaye pe asiko yii ni wọn ri ẹbun ohun agbohunsafẹfẹ lara oun, ti wọn si gba ki oun maa se eto lori redio wọn. O ni awọn ẹbun orin ti ohun tun ni tẹlẹ tun ni oun n lo lati maa mu owo wọle nibẹ nipasẹ ipolowo ọja ati ikede, ti oun si pade oloogbe Kola Olawuyi nibẹ. Ayefele tẹsiwaju pe oun ti sisẹ atagija lẹyin awọn agba osere olorin ri, lara wọn ni Baba Toye Ajagun, Wale Thompson, Micho Ade ati bẹẹ bẹẹ lọ. O ni oun tun maa n ba awọn ile ijọsin ta gita kaakiri lasiko isin pẹlu, ki oun to wa yan isẹ agbohunsafẹfẹ ni aayo. Olayinka Ayefele ni ọjọ Kejila osu Kejila ọdun 1997 ni ijamba se elesu lẹyin ọkọ fun oun, ti oun si bẹrẹ irin ajo orin kikọ. “Osu mọkanla ni mo lo nile iwosan UCH nilu Ibadan fun itọja ara lasiko ti mo ni ijamba ọkọ naa, ti mo si maa n da gbọ awọn orin kekeke ti mo ti kọ tẹlẹ́. Awọn kekeke yii ni mo n gbọ lasiko ti awọn ọrẹ mi wa ki mi, ti wọn si gbe imọran kalẹ pe ka se akojọpọ awọn orin naa, ka si se ifilọlẹ rẹ lati ri owo. Owo yii ni wọn ni maa lo lati lọ fi se itọju ara mi ni oke okun, ti mo si gbe awo orin Bitter Experience jade. Amọ awọn eeyan tẹwọgba orin naa, ti mo si ri pe ọbẹ wa nibẹ, bi mo se bẹrẹ niyẹn. Nigba to n sọ nipa ọpọ ahesọ ọrọ ti awọn eeyan n sọ nipa bo se di olokiki lẹyin to ni ijamba ọkọ tan, Ayefele ni ahesọ ọrọ lasan ni awọn ọrọ naa. “Se o rọrun ki eeyan fi igbesi aye rẹ se oogun okiki tori ko le lowo, ko joko sori kẹkẹ, rara, ko ri bẹẹ. Wọn tun ni mo fi eegun ẹyin mi se oogun okiki ni, ki n wa ni ori kẹkẹ lo wu mi ki n joko si, ẹhun ọrọ lasan ni Koda, wọn tun sọ pe o seese ki n ma le se bii ọkunrin amọ ko ri bẹẹ, mo le se daadaa.” Olayinka Joel Ayefele jẹ akọrin, agbohunsafẹfẹ ati oludasilẹ ileesẹ Redio kaakiri ilẹ Yoruba. Ọmọ bibi ilu Ipoti Ekiti nipinlẹ Ekiti ni, to si dele aye ni ọdun ọjọ kinni osu Keji ọdun 1968, eyiun ọdun mẹrinlelaadọta sẹyin. Ọdun 1997 lo ni ijamba ọkọ to kan eegun ẹyin rẹ, ti ko si le fi ẹsẹ mejeeji rin mọ, eyi to mu ko maa lo kẹkẹ. Yinka Ayefele, ẹni ti ijba apapọ fi ami ẹyẹ MON da lọla lo ti gbe ọpọ awo orin jade, o ni iyawo, to si bi ibẹta. | Yinka Ayefele: Ìrọ́ ni pé ń kò le ṣe bíi ọkùnrin, mò ń ta pútú dàadáa Awọn agba ni ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin, bẹẹ si ni bi ẹni ti yoo ba ni ogo, yoo ri ohun sọ nitori inu ẹgbin ni ọla n gbe. Idi ree ti ilumọọka akọrin ẹmi Tungba nni, Ọmọwe Olayinka Joel Ayefele (MON) fi n se alaye ọpọ ohun ti oju rẹ ri, ko to di eeyan lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ. Ayefele, ninu ifọrọwerọ naa, tun salaye bo se bẹrẹ igbesi aye rẹ, awọn isẹ to ti se, ko to ja oju ọna pẹlu bo se ni ijamba ọkọ to da joko sori kẹkẹ lai le rin. Bakan naa ni gbajumọ akọrin ẹmi ati agbohunsafẹfẹ naa tun sọrọ lori oniruuru ahesọ ọrọ tawọn eeyan n gbe kiri nipa oun lati igba ti ijamba ọkọ naa ti waye. Ayefele salaye fun BBC pe ileesẹ redio ijọba apapọ, ta mọ si Radio Nigeria ni oun ti bẹrẹ isẹ ni ibẹrẹ aye oun. O ni isẹ ki oun maa ba wọn gbe baba Keresi lopin ọdun ni oun kọkọ fi bẹrẹ lọdun 1997, ti wọn si n fun oun ni aadọta naira ni ojumọ. O salaye pe asiko yii ni wọn ri ẹbun ohun agbohunsafẹfẹ lara oun, ti wọn si gba ki oun maa se eto lori redio wọn. O ni awọn ẹbun orin ti ohun tun ni tẹlẹ tun ni oun n lo lati maa mu owo wọle nibẹ nipasẹ ipolowo ọja ati ikede, ti oun si pade oloogbe Kola Olawuyi nibẹ. Ayefele tẹsiwaju pe oun ti sisẹ atagija lẹyin awọn agba osere olorin ri, lara wọn ni Baba Toye Ajagun, Wale Thompson, Micho Ade ati bẹẹ bẹẹ lọ. O ni oun tun maa n ba awọn ile ijọsin ta gita kaakiri lasiko isin pẹlu, ki oun to wa yan isẹ agbohunsafẹfẹ ni aayo. Olayinka Ayefele ni ọjọ Kejila osu Kejila ọdun 1997 ni ijamba se elesu lẹyin ọkọ fun oun, ti oun si bẹrẹ irin ajo orin kikọ. “Osu mọkanla ni mo lo nile iwosan UCH nilu Ibadan fun itọja ara lasiko ti mo ni ijamba ọkọ naa, ti mo si maa n da gbọ awọn orin kekeke ti mo ti kọ tẹlẹ́. Awọn kekeke yii ni mo n gbọ lasiko ti awọn ọrẹ mi wa ki mi, ti wọn si gbe imọran kalẹ pe ka se akojọpọ awọn orin naa, ka si se ifilọlẹ rẹ lati ri owo. Owo yii ni wọn ni maa lo lati lọ fi se itọju ara mi ni oke okun, ti mo si gbe awo orin Bitter Experience jade. Amọ awọn eeyan tẹwọgba orin naa, ti mo si ri pe ọbẹ wa nibẹ, bi mo se bẹrẹ niyẹn. Nigba to n sọ nipa ọpọ ahesọ ọrọ ti awọn eeyan n sọ nipa bo se di olokiki lẹyin to ni ijamba ọkọ tan, Ayefele ni ahesọ ọrọ lasan ni awọn ọrọ naa. “Se o rọrun ki eeyan fi igbesi aye rẹ se oogun okiki tori ko le lowo, ko joko sori kẹkẹ, rara, ko ri bẹẹ. Wọn tun ni mo fi eegun ẹyin mi se oogun okiki ni, ki n wa ni ori kẹkẹ lo wu mi ki n joko si, ẹhun ọrọ lasan ni Koda, wọn tun sọ pe o seese ki n ma le se bii ọkunrin amọ ko ri bẹẹ, mo le se daadaa.” Olayinka Joel Ayefele jẹ akọrin, agbohunsafẹfẹ ati oludasilẹ ileesẹ Redio kaakiri ilẹ Yoruba. Ọmọ bibi ilu Ipoti Ekiti nipinlẹ Ekiti ni, to si dele aye ni ọdun ọjọ kinni osu Keji ọdun 1968, eyiun ọdun mẹrinlelaadọta sẹyin. Ọdun 1997 lo ni ijamba ọkọ to kan eegun ẹyin rẹ, ti ko si le fi ẹsẹ mejeeji rin mọ, eyi to mu ko maa lo kẹkẹ. Yinka Ayefele, ẹni ti ijba apapọ fi ami ẹyẹ MON da lọla lo ti gbe ọpọ awo orin jade, o ni iyawo, to si bi ibẹta. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60329281 |
1entertainment
| Ìdí tí àwọn ìbejì mi, Twinz love ṣe ń rí mi mú fi ṣe “prank” wọn rèé – Ìyá Ìbejì | “A ṣe prank gbe ọkan lara wa loyun fun iya ibeji, wọn sọkun gidi gan, koda bi a ṣe pada sọ pe irọ ni, wọn ṣi balẹ sile iwosan”. Ṣe ẹ ranti bi awọn ibeji yii ṣe ti di gbajumọ lori ayelujara bayii pẹlu orukọ wọn “Twinz Love”?\nỌjọ tun ti gun ọjọ ori wọn ti awọn mejeji si ti n ṣe ọpọlọpọ nkan kun ohun ti wọn ba bẹrẹ iṣẹ adẹrinpoṣonu lori ayelujara. iya to bi Moyinoluwa ati Doyin Oladimeji ti ba BBC Yoruba sọrọ. Lọjọ ti a kọkọ ṣe “Facebook Live pẹlu awọn ibeji naa, iya wọn ko fẹ fi oju han. “Mi o fẹran keeyan wọ aṣọ, ko jẹun, ko maa gbe e si ori afẹfẹ fun gbogbo aye amọ, awọn ọmọ yii...” Arabinrin Adeyinka Oladimeji tun ṣalaye pe lati kekere, oun fun wọn ni aaye lati sunmọ oun daadaa. “Mo ni aaye fun wọn lati sun mọ mi ni gbogbo ọna tori naa ẹru kii ba wọn lati sun mọ mi tabi sọ ọrọ nipa ara wọn fun mi”. Bi awọn naa ṣe n ṣalaye bi wọn ṣe de oke ninu iṣẹ ti wọn yan. Wọn ni awọn ko kọkọ ri eeyan to fẹran nkan ti awọn fi sita amọ o pada yi biri ti “likes” n tu puupuu. Kehinde: Lori Instagram, a kọkọ lo Moyin&Doyin amọ Instagram kọọ, mo kan ronu ni pe ṣebi ibeji ni wa a dẹ fẹran ara wa, bi Twinz Love ṣe jade niyẹn ti gbogbo eeyan fẹran ẹ. Bi wọ́n ṣe jẹ́ gbajúmọ̀ tó, wọn kawe tan ni Fasiti amọ awọn mejeeji gan ko ri iṣẹ. Taiye: Bi emi nisinyi, mo ka “History and International Relations” ni ile ẹkọ amọ, mo maa n ji lati din ipapanu Doughnut laraarọ ni. Iya wọn taa ba sọrọ naa sọ iriri rẹ nipa ere ẹfẹ kan ti wọn ti sọ fun oun pe ọkan lara wọn loyun eyi to lagbara gan. O ni ọjọ naa dabii pe opin ti de ba gbogbo laalaa oun lori wọn. Lootọ, lọpọ igba kii tete mọ pe ere ni wọn n ṣe. “Ti mo ba sọ fawọn eeyan pe ọpọlọpọ nkan ti wọn ṣe yii, mi o mọ nipa rẹ rara. Omii gan wọn o le fi sita tori igba mii ti mo ba ti mọ, mo ma n daa ru fun wọn gidi gan ti mo maa binu”. | Ìdí tí àwọn ìbejì mi, Twinz love ṣe ń rí mi mú fi ṣe “prank” wọn rèé – Ìyá Ìbejì “A ṣe prank gbe ọkan lara wa loyun fun iya ibeji, wọn sọkun gidi gan, koda bi a ṣe pada sọ pe irọ ni, wọn ṣi balẹ sile iwosan”. Ṣe ẹ ranti bi awọn ibeji yii ṣe ti di gbajumọ lori ayelujara bayii pẹlu orukọ wọn “Twinz Love”?\nỌjọ tun ti gun ọjọ ori wọn ti awọn mejeji si ti n ṣe ọpọlọpọ nkan kun ohun ti wọn ba bẹrẹ iṣẹ adẹrinpoṣonu lori ayelujara. iya to bi Moyinoluwa ati Doyin Oladimeji ti ba BBC Yoruba sọrọ. Lọjọ ti a kọkọ ṣe “Facebook Live pẹlu awọn ibeji naa, iya wọn ko fẹ fi oju han. “Mi o fẹran keeyan wọ aṣọ, ko jẹun, ko maa gbe e si ori afẹfẹ fun gbogbo aye amọ, awọn ọmọ yii...” Arabinrin Adeyinka Oladimeji tun ṣalaye pe lati kekere, oun fun wọn ni aaye lati sunmọ oun daadaa. “Mo ni aaye fun wọn lati sun mọ mi ni gbogbo ọna tori naa ẹru kii ba wọn lati sun mọ mi tabi sọ ọrọ nipa ara wọn fun mi”. Bi awọn naa ṣe n ṣalaye bi wọn ṣe de oke ninu iṣẹ ti wọn yan. Wọn ni awọn ko kọkọ ri eeyan to fẹran nkan ti awọn fi sita amọ o pada yi biri ti “likes” n tu puupuu. Kehinde: Lori Instagram, a kọkọ lo Moyin&Doyin amọ Instagram kọọ, mo kan ronu ni pe ṣebi ibeji ni wa a dẹ fẹran ara wa, bi Twinz Love ṣe jade niyẹn ti gbogbo eeyan fẹran ẹ. Bi wọ́n ṣe jẹ́ gbajúmọ̀ tó, wọn kawe tan ni Fasiti amọ awọn mejeeji gan ko ri iṣẹ. Taiye: Bi emi nisinyi, mo ka “History and International Relations” ni ile ẹkọ amọ, mo maa n ji lati din ipapanu Doughnut laraarọ ni. Iya wọn taa ba sọrọ naa sọ iriri rẹ nipa ere ẹfẹ kan ti wọn ti sọ fun oun pe ọkan lara wọn loyun eyi to lagbara gan. O ni ọjọ naa dabii pe opin ti de ba gbogbo laalaa oun lori wọn. Lootọ, lọpọ igba kii tete mọ pe ere ni wọn n ṣe. “Ti mo ba sọ fawọn eeyan pe ọpọlọpọ nkan ti wọn ṣe yii, mi o mọ nipa rẹ rara. Omii gan wọn o le fi sita tori igba mii ti mo ba ti mọ, mo ma n daa ru fun wọn gidi gan ti mo maa binu”. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/ck5zyy5319eo |
1entertainment
| Pasuma: Ọ̀gáńlá Fújì ní ominú ń kọ òun lórí ọ̀dá àwọn ìràwọ̀ tuntun lágbo orin Fújì | Gbajugbaja akọrin Fuji ni, Alhaji Wasiu Alabi ti ọpọ eeyan mọ si Pasuma Wonder, iba wasi baba baraka ti ṣalaye pe ọrọ iyawo nini fun oun kii ṣe afi waduwadu ṣe o. Alhaji Pasuma ṣalaye pe idi ti oun ko tii fi ni iyawo lọwọ yii naa ni pe oun fẹ ṣe ohun gbogbo bi o ti yẹ ko le baa ri bose yẹ ko ri. Paso ni ohun lawọn obinrin to bimọ fun oun o, ṣugbọn ọrọ iyawo afẹsile ko tii yọ fun oun bayii. Ọganla Fuji ni nigba to ba ya oun yoo niyawo ṣugbọn suuru lo gba. Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba ni Ba wasi ti sọ ọrọ yii. Bakan naa lo sọrọ lori ahesọ ọrọ to n wi pe ọjọṣepọ ifẹ n bẹ laarin oun ati gbajumọ oṣere tiata, Jaiye Kuti. Pasuma ni ere tiata lo da awọn mejeeji pọ. Bakan naa lo fi kun un pe ọrẹ lasan loun ati gbajugbaja oṣere tiata, Ronkẹ Ididowo ti ko si si ohun ifẹ ikọkọ kankan to pa wọn pọ. Bakan naa lo kọminu lori ọda awọn irawọ tuntun lagbo fuji. O ni ohun to mi oun lọkan ni bi o ṣe jẹ pe awọn ọdọ olorin ko fẹ kọ orin Fuji mọ bi ko ṣe orin takasufe, HipHop. O fi kun un pe oun yoo sa ipa oun gẹgẹ bii aṣiwaju lati mu idagbasoke ba awọn ọdọ to ba fẹ yan orin Fuji laayo | Pasuma: Ọ̀gáńlá Fújì ní ominú ń kọ òun lórí ọ̀dá àwọn ìràwọ̀ tuntun lágbo orin Fújì Gbajugbaja akọrin Fuji ni, Alhaji Wasiu Alabi ti ọpọ eeyan mọ si Pasuma Wonder, iba wasi baba baraka ti ṣalaye pe ọrọ iyawo nini fun oun kii ṣe afi waduwadu ṣe o. Alhaji Pasuma ṣalaye pe idi ti oun ko tii fi ni iyawo lọwọ yii naa ni pe oun fẹ ṣe ohun gbogbo bi o ti yẹ ko le baa ri bose yẹ ko ri. Paso ni ohun lawọn obinrin to bimọ fun oun o, ṣugbọn ọrọ iyawo afẹsile ko tii yọ fun oun bayii. Ọganla Fuji ni nigba to ba ya oun yoo niyawo ṣugbọn suuru lo gba. Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba ni Ba wasi ti sọ ọrọ yii. Bakan naa lo sọrọ lori ahesọ ọrọ to n wi pe ọjọṣepọ ifẹ n bẹ laarin oun ati gbajumọ oṣere tiata, Jaiye Kuti. Pasuma ni ere tiata lo da awọn mejeeji pọ. Bakan naa lo fi kun un pe ọrẹ lasan loun ati gbajugbaja oṣere tiata, Ronkẹ Ididowo ti ko si si ohun ifẹ ikọkọ kankan to pa wọn pọ. Bakan naa lo kọminu lori ọda awọn irawọ tuntun lagbo fuji. O ni ohun to mi oun lọkan ni bi o ṣe jẹ pe awọn ọdọ olorin ko fẹ kọ orin Fuji mọ bi ko ṣe orin takasufe, HipHop. O fi kun un pe oun yoo sa ipa oun gẹgẹ bii aṣiwaju lati mu idagbasoke ba awọn ọdọ to ba fẹ yan orin Fuji laayo | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51780573 |
3politics
| Ekiti state PDP Congress: Fayose, Olujimi, Oni ń forígbárí nítorí ìdìbò wọ́ọ̀dù tó wáyé lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP l'Ekiti | Ina edeaiyede n jo laarin awọn eekan oloṣelu lẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ekiti paapaa laarin igun gomina tẹlẹ, Ayọ Fayose ati igbakeji rẹ nigbakan ri to tun jẹ sẹnetọ lọwọ bayii nileegbimọ aṣofin apapọ Naijiria. Ko si ohun meji to n fa awuyewuye laarin wọn ju abajade eto idibo ati yan awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọọdu to waye nipinlẹ Ekiti lọjọ Satide, ọjọ karundinlogun oṣu kinni ọdun 2022. Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Sẹnetọ Abiọdun Olujimi ṣalaye pe lara ọna ati mu iṣọkan igbọraẹniye ati alaafia pada sagbo ẹgbẹ naa nipinlẹ Ekiti lawọn fi wo eto naa. O ni igbagbọ awọn ṣaaju eto naa ni pe gbogbo ẹgun iṣaaju to da wahala silẹ ni wọn yoo dana sun. Amọsa, o ni ọrọ ko ri bẹẹ nigba ti awọn rii pe meji ninu awọn eeyan to wa nidi wahala naa lati ipilẹ wa ni wọn tun yan lati ṣe akoso idibo aṣoju naa. Sẹnatọ Abiọdun Olujimi fi ẹsun kan Oloye Ayọ Fayose pe oun gan ni eku ẹda to n da ina alaafia PDP ru paapa pẹlu ti idibo aṣoju wọọdu naa. Sẹnetọ naa ṣalaye pe inu kọrọ ile kan ni awọn igun OPA to jẹ ti Fayoṣe ti kọ orukọ awọn aṣoju ti wọn fẹ laifi ti awọn igun ti 'Repositioning' to wa pẹlu Olujimi ṣe. Amọṣa ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, gomina tẹlẹ nipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe ṣalaye pe oun o ba ẹnikẹni ja. O ni eeyan oun ni gbogbo wọn, oun ko si tii ṣe ohnunkohun to buru gẹgẹ bii aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu naa. Fayoṣe ṣalaye pe oun o mọ idi ti awọn oludije ti ọrọ kan ṣe n pariwo oun nigba ti wọn mọ pe oun kii ṣe Oludije. Oṣoko, gẹgẹ bi orukọ inagijẹ ti ọpọ maa n pe e ṣalaye pe niwọn igba to jẹ wi pe nitori pe awọn oludije naa ri oun gẹgẹ bii eeyan pataki lagbo oṣelu ni wọn fi n da orukọ oun. O ni gbogbo awọn ileeṣẹ agbofinro ni wọn ni akọsilẹ pe eto idibo ati yan awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọọdu waye nipinlẹ Ekiti, oun kọ lo si gba wọn siṣẹ. Lara awọn eekan oloṣelu ni ipinlẹ Ekiti to n gbaradi lati dije fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ekiti, Biọdun Olujimi ati Ṣẹgun Oni fọn si igboro ilu Ado Ekiti lati ṣe iwọde takogomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Ayọdele Fayose. Ẹsun ti wọn n fi kan Fayose ni pe o ti n dọwọ ru pẹlu ibo yiyan awọn adari ati aṣoju ẹgbẹ naa lẹsẹpupu wọọdu eyi to waye lọjọ Satide ọjọ karundinlogun, oṣu Kinni dun 2022. Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan dara pọ wọ iwọde naa ti wọn si n ke sawọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa lati fofin de Fayoṣe lẹgbẹ oṣelu naa. Wọn ni o n ṣe agbẹyinbẹbọjẹ fun gbogbo ilakaka awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa nipa dida ṣe idibo yiyan awọn adari wọdu ni gbọngan adani rẹ kan lasiko to si jẹ pe ipade idibo ti ẹgbẹ fọwọ si gan n lọ kaakiri awọn wọọdu mẹtadinlọgọsan nipinlẹ naa. Awọn oludije mejeeji naa wa ke sawọn adari ẹgbẹ oṣelu naa lati maṣẹ fọwọ kan iwe orukọ awọn adari wọọdu yoowu ti Ayọdele Fayose ba fi ranṣẹ si wọn nitori pe, ni ti awọn o, ipade idibo yiyan adari ẹgbẹ oṣelu PDP lawọn wọọdu nipinlẹ Ekiti ko waye. Awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn ti tẹwọ gba abajade ipade idibo yiyan awọn adari ati aṣoju ẹgbẹ naa lẹsẹpupu wọọdu lati ipinlẹ Ekiti. Ninu atẹjade kan ti wọn fi si oju opo ikanni Twitter ẹgbẹ oṣelu PDP awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa ni awọn yoo wa ojutu si awọn aawọ to suyọ lasiko ipade idibo naa. Atẹjade ọhun ti alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP lapapọ, Debọ Ologunagba fọwọ si ṣalaye pe bi wọn ṣe n tẹwọ gba esi idibo naa ni wọn tun tẹwọ gba awọn iwe ẹhonu latọdọ awọn mọ ẹgbẹ to ni ẹhonu kan kabi omiran. O ni gbogbo rẹ ni wọn yoo yẹwo lati rii daju pe alaafia n jọba. | Ekiti state PDP Congress: Fayose, Olujimi, Oni ń forígbárí nítorí ìdìbò wọ́ọ̀dù tó wáyé lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP l'Ekiti Ina edeaiyede n jo laarin awọn eekan oloṣelu lẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ekiti paapaa laarin igun gomina tẹlẹ, Ayọ Fayose ati igbakeji rẹ nigbakan ri to tun jẹ sẹnetọ lọwọ bayii nileegbimọ aṣofin apapọ Naijiria. Ko si ohun meji to n fa awuyewuye laarin wọn ju abajade eto idibo ati yan awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọọdu to waye nipinlẹ Ekiti lọjọ Satide, ọjọ karundinlogun oṣu kinni ọdun 2022. Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Sẹnetọ Abiọdun Olujimi ṣalaye pe lara ọna ati mu iṣọkan igbọraẹniye ati alaafia pada sagbo ẹgbẹ naa nipinlẹ Ekiti lawọn fi wo eto naa. O ni igbagbọ awọn ṣaaju eto naa ni pe gbogbo ẹgun iṣaaju to da wahala silẹ ni wọn yoo dana sun. Amọsa, o ni ọrọ ko ri bẹẹ nigba ti awọn rii pe meji ninu awọn eeyan to wa nidi wahala naa lati ipilẹ wa ni wọn tun yan lati ṣe akoso idibo aṣoju naa. Sẹnatọ Abiọdun Olujimi fi ẹsun kan Oloye Ayọ Fayose pe oun gan ni eku ẹda to n da ina alaafia PDP ru paapa pẹlu ti idibo aṣoju wọọdu naa. Sẹnetọ naa ṣalaye pe inu kọrọ ile kan ni awọn igun OPA to jẹ ti Fayoṣe ti kọ orukọ awọn aṣoju ti wọn fẹ laifi ti awọn igun ti 'Repositioning' to wa pẹlu Olujimi ṣe. Amọṣa ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, gomina tẹlẹ nipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe ṣalaye pe oun o ba ẹnikẹni ja. O ni eeyan oun ni gbogbo wọn, oun ko si tii ṣe ohnunkohun to buru gẹgẹ bii aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu naa. Fayoṣe ṣalaye pe oun o mọ idi ti awọn oludije ti ọrọ kan ṣe n pariwo oun nigba ti wọn mọ pe oun kii ṣe Oludije. Oṣoko, gẹgẹ bi orukọ inagijẹ ti ọpọ maa n pe e ṣalaye pe niwọn igba to jẹ wi pe nitori pe awọn oludije naa ri oun gẹgẹ bii eeyan pataki lagbo oṣelu ni wọn fi n da orukọ oun. O ni gbogbo awọn ileeṣẹ agbofinro ni wọn ni akọsilẹ pe eto idibo ati yan awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọọdu waye nipinlẹ Ekiti, oun kọ lo si gba wọn siṣẹ. Lara awọn eekan oloṣelu ni ipinlẹ Ekiti to n gbaradi lati dije fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ekiti, Biọdun Olujimi ati Ṣẹgun Oni fọn si igboro ilu Ado Ekiti lati ṣe iwọde takogomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Ayọdele Fayose. Ẹsun ti wọn n fi kan Fayose ni pe o ti n dọwọ ru pẹlu ibo yiyan awọn adari ati aṣoju ẹgbẹ naa lẹsẹpupu wọọdu eyi to waye lọjọ Satide ọjọ karundinlogun, oṣu Kinni dun 2022. Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan dara pọ wọ iwọde naa ti wọn si n ke sawọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa lati fofin de Fayoṣe lẹgbẹ oṣelu naa. Wọn ni o n ṣe agbẹyinbẹbọjẹ fun gbogbo ilakaka awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa nipa dida ṣe idibo yiyan awọn adari wọdu ni gbọngan adani rẹ kan lasiko to si jẹ pe ipade idibo ti ẹgbẹ fọwọ si gan n lọ kaakiri awọn wọọdu mẹtadinlọgọsan nipinlẹ naa. Awọn oludije mejeeji naa wa ke sawọn adari ẹgbẹ oṣelu naa lati maṣẹ fọwọ kan iwe orukọ awọn adari wọọdu yoowu ti Ayọdele Fayose ba fi ranṣẹ si wọn nitori pe, ni ti awọn o, ipade idibo yiyan adari ẹgbẹ oṣelu PDP lawọn wọọdu nipinlẹ Ekiti ko waye. Awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn ti tẹwọ gba abajade ipade idibo yiyan awọn adari ati aṣoju ẹgbẹ naa lẹsẹpupu wọọdu lati ipinlẹ Ekiti. Ninu atẹjade kan ti wọn fi si oju opo ikanni Twitter ẹgbẹ oṣelu PDP awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa ni awọn yoo wa ojutu si awọn aawọ to suyọ lasiko ipade idibo naa. Atẹjade ọhun ti alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP lapapọ, Debọ Ologunagba fọwọ si ṣalaye pe bi wọn ṣe n tẹwọ gba esi idibo naa ni wọn tun tẹwọ gba awọn iwe ẹhonu latọdọ awọn mọ ẹgbẹ to ni ẹhonu kan kabi omiran. O ni gbogbo rẹ ni wọn yoo yẹwo lati rii daju pe alaafia n jọba. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60034883 |
5sports
| Mama Arsenal: Ẹgbẹ́ kan ti fún màmá ní ẹ̀bùn owó | Bi a ba ku, iṣe o tan ni Yoruba maa n wi. Bẹẹ gẹlẹ ni ọrọ ri pẹlu mama agba ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Nosimatu Hassan. Mama to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin di ẹni ti ọgọọrọ eeyan n sọ nipa rẹ lori ayelujara lẹyin ti sọ ọpọ ọrọ nipa ẹgbẹ agbabọọlu to yan laayo. Lati igba naa ọpọ ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria ti n ṣeleri lati fun mama ni ẹbun kan tabi omiiran. Ṣugbọn ni bayii, ẹgbẹ ololufẹ awọn ikọ agbabọọlu Naijiria, Authentic Nigeria Supporters' Club ti fun mama ni ẹbun owo rọgun rọgun. Owo ti ẹgbẹ ololufẹ agbabọọlu Naijiria naa fun mama Arsenal ni ṣe ẹgbẹrun un lọna ọta le lugba o din mẹwaa. Ọlọ́run ló yàn mí ti Arsenal, mi ò lè fi wọ́n sílẹ̀ láéláé- Mama Arsenal yarí Ara meriri , mo ri ori ologbo lori atẹ ni ọrọ mama agba kan, Nosimatu Hazzan, ti ọpọ eeyan mọ si mama Arsenal. Mama agba yii, to nifẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal bii oju, ti ọjọ ori rẹ yoo si to aadọrin ọdun, lo nifẹ ere bọọlu ju ọmọde tabi awọn ọkunrin miran lọ. Lasiko ti BBC se abẹwo si ọdọ mama naa, ti ọpọ eeyan mọ si Mama Arsenal nitori bo se nifẹ si ẹgbẹ agbabọslu Arsenal, ẹnu ko gba iroyin. Ko fẹẹ si agbabọọlu Arsenal tẹlẹ abi lọwọlọwọ bayii ti mama naa ko lee darukọ, to si ni oun maa n wo bọọlu ninu ile oun tabi lọ sawọn ibudo ti wọn ti n wo bọọlu. Bakan naa lo ni oun maa n lọ sawọn papa isere idaraya nilu Eko lati wo ere bọọlu, ti oun si nifẹ ere sisa, awọn ere idaraya miran lorisirisi, paapaa ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal. | Mama Arsenal: Ẹgbẹ́ kan ti fún màmá ní ẹ̀bùn owó Bi a ba ku, iṣe o tan ni Yoruba maa n wi. Bẹẹ gẹlẹ ni ọrọ ri pẹlu mama agba ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Nosimatu Hassan. Mama to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin di ẹni ti ọgọọrọ eeyan n sọ nipa rẹ lori ayelujara lẹyin ti sọ ọpọ ọrọ nipa ẹgbẹ agbabọọlu to yan laayo. Lati igba naa ọpọ ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria ti n ṣeleri lati fun mama ni ẹbun kan tabi omiiran. Ṣugbọn ni bayii, ẹgbẹ ololufẹ awọn ikọ agbabọọlu Naijiria, Authentic Nigeria Supporters' Club ti fun mama ni ẹbun owo rọgun rọgun. Owo ti ẹgbẹ ololufẹ agbabọọlu Naijiria naa fun mama Arsenal ni ṣe ẹgbẹrun un lọna ọta le lugba o din mẹwaa. Ọlọ́run ló yàn mí ti Arsenal, mi ò lè fi wọ́n sílẹ̀ láéláé- Mama Arsenal yarí Ara meriri , mo ri ori ologbo lori atẹ ni ọrọ mama agba kan, Nosimatu Hazzan, ti ọpọ eeyan mọ si mama Arsenal. Mama agba yii, to nifẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal bii oju, ti ọjọ ori rẹ yoo si to aadọrin ọdun, lo nifẹ ere bọọlu ju ọmọde tabi awọn ọkunrin miran lọ. Lasiko ti BBC se abẹwo si ọdọ mama naa, ti ọpọ eeyan mọ si Mama Arsenal nitori bo se nifẹ si ẹgbẹ agbabọslu Arsenal, ẹnu ko gba iroyin. Ko fẹẹ si agbabọọlu Arsenal tẹlẹ abi lọwọlọwọ bayii ti mama naa ko lee darukọ, to si ni oun maa n wo bọọlu ninu ile oun tabi lọ sawọn ibudo ti wọn ti n wo bọọlu. Bakan naa lo ni oun maa n lọ sawọn papa isere idaraya nilu Eko lati wo ere bọọlu, ti oun si nifẹ ere sisa, awọn ere idaraya miran lorisirisi, paapaa ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-53304170 |
3politics
| Shuahib Afolabi Salisu: Òótọ́ ni mo súnmọ́ Gómìnà ṣùgbọ́n mo kúnjú òṣùwọ̀n ni mo ṣe gba láti díje dupò | Ẹgbẹ APC nikan lo fẹ́ ẹ ku ninu gbogbo ẹgbẹ nipainlẹ Ogun bayii- Omo Yayi Alhaji Shuahib Afolabi Salisu to n dije dupo aṣojuṣofin fun ẹkun aarin gbungbun ipinle Ogun ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ Ogun bayii. O mẹnuba iriri rẹ ninu oṣelu lati kekere titi di asiko yii. O sọ awọn ipenija, aṣẹyọri ati ikuna to ti koju ninu iṣelu titi di asiko yii ki awọn ọdọ le kọ ẹkọ ti o yẹ. Omọ Yayi tun ṣalaye ohun to ni lọkan lati ṣe fun ọdọ, awọn obinrin ati awọn Oludibo lapapọ. O mẹnuba ohun to maa jẹ ki ara rọ gbogbo ilu lasiko yii. Bakan naa ni Shuahib Afolabi Salisu sọrọ lori ibi ti iselu ipinlẹ Ogun dẹ duro ati ajọṣepọ to wa laarin Gomina Dapo Abiodun ati awọn ẹka iṣẹjoba to ku nibẹ. O ni pe ko si rukerudo ninu ile igbimọ Aṣofin ni ipinlẹ Ogun bayii. | Shuahib Afolabi Salisu: Òótọ́ ni mo súnmọ́ Gómìnà ṣùgbọ́n mo kúnjú òṣùwọ̀n ni mo ṣe gba láti díje dupò Ẹgbẹ APC nikan lo fẹ́ ẹ ku ninu gbogbo ẹgbẹ nipainlẹ Ogun bayii- Omo Yayi Alhaji Shuahib Afolabi Salisu to n dije dupo aṣojuṣofin fun ẹkun aarin gbungbun ipinle Ogun ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ Ogun bayii. O mẹnuba iriri rẹ ninu oṣelu lati kekere titi di asiko yii. O sọ awọn ipenija, aṣẹyọri ati ikuna to ti koju ninu iṣelu titi di asiko yii ki awọn ọdọ le kọ ẹkọ ti o yẹ. Omọ Yayi tun ṣalaye ohun to ni lọkan lati ṣe fun ọdọ, awọn obinrin ati awọn Oludibo lapapọ. O mẹnuba ohun to maa jẹ ki ara rọ gbogbo ilu lasiko yii. Bakan naa ni Shuahib Afolabi Salisu sọrọ lori ibi ti iselu ipinlẹ Ogun dẹ duro ati ajọṣepọ to wa laarin Gomina Dapo Abiodun ati awọn ẹka iṣẹjoba to ku nibẹ. O ni pe ko si rukerudo ninu ile igbimọ Aṣofin ni ipinlẹ Ogun bayii. | https://www.bbc.com/yoruba/63658710 |
5sports
| Odion Ighalo: Ó di 2021 kí Ighalo tó fi Manchester United | Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti sọ idi ti wọn fi ṣe adehun tuntun pẹlu ẹlẹsẹ ayo, Odion Ighalo eyi ti yoo mu un di oṣu ọdun 2021 pẹlu ikọ naa. Lori opo ayelujara ikansiraẹni Twitter ni Man U ti fidi ọrọ naa mulẹ lọjọ Aje. Lasiko ti ọja rira agbabọọlu ṣi silẹ ninu oṣu kinni ọdun 2020 ni Ighalo darapọ mọ Manchester United lati ikọ agbabọọlu China, Shanghai Shenhua. Ighalo ti gba goolu mẹrin sawọn lẹẹmẹrin ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹjọ to lanfaani lati ṣoju Man U ninu rẹ ki o to di wi pe wọn so ere bọọlu rọ nilẹ Gẹẹsi nitori ajakalẹ aarun coronavirus. Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Man U ti sọ loju opo Twitter pe ohun to jẹ kawọn ṣe adehun tuntun pẹlu Ighalo ni pe o farajin ṣiṣẹ atawọn goolu to ti gba sawọn. Ti ẹ ko ba gbagbe, Ighalo gan an fun ra rẹ ṣalaye laipẹ yii bi o ti fi owo ounjẹ ọsan rẹ lọ wo ere bọọlu Man U. O ni oun atawọn ẹgbọn ati aburo oun maa n ya owo sọtọ ninu owo ounjẹ lati le lanfaani wo Manchester United. Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Man U, Ole Gunnar Solskjaer sọ pe oun fẹ ki Ighalo gba ife ẹyẹ pẹlu Man U ko to fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ. | Odion Ighalo: Ó di 2021 kí Ighalo tó fi Manchester United Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti sọ idi ti wọn fi ṣe adehun tuntun pẹlu ẹlẹsẹ ayo, Odion Ighalo eyi ti yoo mu un di oṣu ọdun 2021 pẹlu ikọ naa. Lori opo ayelujara ikansiraẹni Twitter ni Man U ti fidi ọrọ naa mulẹ lọjọ Aje. Lasiko ti ọja rira agbabọọlu ṣi silẹ ninu oṣu kinni ọdun 2020 ni Ighalo darapọ mọ Manchester United lati ikọ agbabọọlu China, Shanghai Shenhua. Ighalo ti gba goolu mẹrin sawọn lẹẹmẹrin ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹjọ to lanfaani lati ṣoju Man U ninu rẹ ki o to di wi pe wọn so ere bọọlu rọ nilẹ Gẹẹsi nitori ajakalẹ aarun coronavirus. Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Man U ti sọ loju opo Twitter pe ohun to jẹ kawọn ṣe adehun tuntun pẹlu Ighalo ni pe o farajin ṣiṣẹ atawọn goolu to ti gba sawọn. Ti ẹ ko ba gbagbe, Ighalo gan an fun ra rẹ ṣalaye laipẹ yii bi o ti fi owo ounjẹ ọsan rẹ lọ wo ere bọọlu Man U. O ni oun atawọn ẹgbọn ati aburo oun maa n ya owo sọtọ ninu owo ounjẹ lati le lanfaani wo Manchester United. Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Man U, Ole Gunnar Solskjaer sọ pe oun fẹ ki Ighalo gba ife ẹyẹ pẹlu Man U ko to fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/media-52887815 |
3politics
| Iná sọ nílé Akin Ogunbiyi tó ń díje du ípò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Osun, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò | Ina ti jo ile oludije sipo gomina nipinlẹ Osun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord, Akin Ogunbiyi. Iroyin ni aarọ kutu ọjọ Isinimi ni ina ọhun dede ṣẹyọ, to si ba ile naa atawọn dukia mii to wa ninu ọhun jẹ ni Ileogbo, to wa ni ijọba ibilẹ Ayedire. Ile ọhun, to dojukọ ọọfisi ijọba ibilẹ Ayedire ni Ogunbi sọ pe oun ko mọ ohun to ṣokunfa bi ina ṣe sọ nibẹ. Nigba ti BBC Yoruba kan si Ogunbiyi, agbẹnusọ rẹ, Steven Owolabi ṣalayae pe ile ijọsin ni oludije naa wa ki wọn to ke si pe ina ti sọ ninu ile rẹ. O ni “Lootọ ni ina jo ile naa, amọ a ti yanju gbogbo rẹ.” “A ko mọ ohun to ṣokunfa ina naa titi di asiko yii, bẹẹ ina ọhun kii ṣe ina kekere.” “Inu yara rẹ ni ina naa ti bẹrẹ, gbogbo yara naa lo jona, bẹẹ naa ni awọn iwe kan to ṣe pataki ba ina ọhun lọ.” Owolabi ṣalaye siwaju si pe “Ọna ile ijọsin ló wa ki wọn to ke si pe ile rẹ ti n jona, adupẹ lọwọ Ọlọrun pe kii ṣe oru ọganjọ ni ina ọhun ṣẹyọ, ohun ti a n sọ bayii kọ ni a ba maa sọ... nitori ko si nnkankan to ṣeku ninu yara yẹn.” O pari ọrọ rẹ pe ko si ẹnikẹni to farapa ninu ijamba ina ọhun. | Iná sọ nílé Akin Ogunbiyi tó ń díje du ípò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Osun, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò Ina ti jo ile oludije sipo gomina nipinlẹ Osun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord, Akin Ogunbiyi. Iroyin ni aarọ kutu ọjọ Isinimi ni ina ọhun dede ṣẹyọ, to si ba ile naa atawọn dukia mii to wa ninu ọhun jẹ ni Ileogbo, to wa ni ijọba ibilẹ Ayedire. Ile ọhun, to dojukọ ọọfisi ijọba ibilẹ Ayedire ni Ogunbi sọ pe oun ko mọ ohun to ṣokunfa bi ina ṣe sọ nibẹ. Nigba ti BBC Yoruba kan si Ogunbiyi, agbẹnusọ rẹ, Steven Owolabi ṣalayae pe ile ijọsin ni oludije naa wa ki wọn to ke si pe ina ti sọ ninu ile rẹ. O ni “Lootọ ni ina jo ile naa, amọ a ti yanju gbogbo rẹ.” “A ko mọ ohun to ṣokunfa ina naa titi di asiko yii, bẹẹ ina ọhun kii ṣe ina kekere.” “Inu yara rẹ ni ina naa ti bẹrẹ, gbogbo yara naa lo jona, bẹẹ naa ni awọn iwe kan to ṣe pataki ba ina ọhun lọ.” Owolabi ṣalaye siwaju si pe “Ọna ile ijọsin ló wa ki wọn to ke si pe ile rẹ ti n jona, adupẹ lọwọ Ọlọrun pe kii ṣe oru ọganjọ ni ina ọhun ṣẹyọ, ohun ti a n sọ bayii kọ ni a ba maa sọ... nitori ko si nnkankan to ṣeku ninu yara yẹn.” O pari ọrọ rẹ pe ko si ẹnikẹni to farapa ninu ijamba ina ọhun. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cjk0d566d02o |
1entertainment
| Kunle Adeyanju ti gun orí àpáta Kilimanjaro rí, ó sì ti gun alùpùpù láti Naijiria lọ sí Ghana | Arakunrin ọmọ orileede Naijiria to n gun alaupupu bọ lati London ti balẹ si Naijiria bayii. Kunle Adeyanju bẹrẹ irinajo yi lati London to si kan si awọn orileede Afrika ko to de ilẹ baba rẹ lọjọ Aiku yi. Nise lawọn eeyan to ti n fi ọkan ba irinajo rẹ bọ tu yaya jade lati wa pade rẹ Ni ibode Naijiria pẹlu orileede Benin to wa ni Seme ni awọn ololufẹ rẹ ti wa ki kaabọ. Shina Peller àti Teslim Folarin tahùn síra wọn lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn, wàhálà ṣẹlẹ̀ n'ídìbò abẹ́nú Oyo 'Ìdí rèé tí mo fi ń sin ẹkùn méjì nínú ilé mí' "Kunle Adeyanju ti gun orí àpáta Kilimanjaro rí, ó sì ti gun alùpùpù láti Naijiria lọ sí Ghana". Ọmọ Naijiria to n wa alupupu lati ilu London nilẹ Gẹẹsi, siluu Eko ni Naijiria, Kunle Adeyanju ti ṣalaye eredi to ṣe gbe igbesẹ naa. Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Adeyanju ni ọna ati tan iṣoro awọn eeyan lo mu ki oun gbe igbesẹ naa. O ni oun tun gbe igbesẹ ọhun nitori oun jẹ ẹnikan to fẹran lati maa rin irinajo to le. Kunle Adeyanju sọ fun BBC Yoruba pe kii ṣe igba akọkọ ree ti oun yoo gun alupupu lati orilẹ-ede kan si omiran. O ni ''Mo fẹran lati maa ṣe awon ohun akinkanju, mo si fẹran irinajo to le.'' ''Mo ti gun ori apata Kilimanjaro ri, eyii to jẹ ori apata to ga julọ nilẹ Afrika.'' ''Bakan naa ni mo ti wa alupupu lati Naijiria lọ si orilẹ-ede Ghana ri, ti mo tun gun alupupu pada wa si Naijiria.'' ''Nigba ti mo pinnu lati rin irinajo yii lati ilu London si Naijiria, mo woye pe bawo ni mo ṣe le ṣe lati fi tu awọn eeyan lọrun ki n si fi ṣe awọn araalu loore.'' O ni yatọ si pe oun fẹran awọn irinajo to le, oun tun gunle irinajo naa lati ṣe ikowojọ fun awọn alaini, ati lati fi gbogun ti aisan to n ba awọn eeyan finra bii polio. Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 yii ni Adeyanju gbera kuro niluu London pẹlu alupupu rẹ, ti ireti ṣi wa pe yoo gunlẹ si Naijiria lọjọ Isinmi, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2022. | Kunle Adeyanju ti gun orí àpáta Kilimanjaro rí, ó sì ti gun alùpùpù láti Naijiria lọ sí Ghana Arakunrin ọmọ orileede Naijiria to n gun alaupupu bọ lati London ti balẹ si Naijiria bayii. Kunle Adeyanju bẹrẹ irinajo yi lati London to si kan si awọn orileede Afrika ko to de ilẹ baba rẹ lọjọ Aiku yi. Nise lawọn eeyan to ti n fi ọkan ba irinajo rẹ bọ tu yaya jade lati wa pade rẹ Ni ibode Naijiria pẹlu orileede Benin to wa ni Seme ni awọn ololufẹ rẹ ti wa ki kaabọ. Shina Peller àti Teslim Folarin tahùn síra wọn lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn, wàhálà ṣẹlẹ̀ n'ídìbò abẹ́nú Oyo 'Ìdí rèé tí mo fi ń sin ẹkùn méjì nínú ilé mí' "Kunle Adeyanju ti gun orí àpáta Kilimanjaro rí, ó sì ti gun alùpùpù láti Naijiria lọ sí Ghana". Ọmọ Naijiria to n wa alupupu lati ilu London nilẹ Gẹẹsi, siluu Eko ni Naijiria, Kunle Adeyanju ti ṣalaye eredi to ṣe gbe igbesẹ naa. Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Adeyanju ni ọna ati tan iṣoro awọn eeyan lo mu ki oun gbe igbesẹ naa. O ni oun tun gbe igbesẹ ọhun nitori oun jẹ ẹnikan to fẹran lati maa rin irinajo to le. Kunle Adeyanju sọ fun BBC Yoruba pe kii ṣe igba akọkọ ree ti oun yoo gun alupupu lati orilẹ-ede kan si omiran. O ni ''Mo fẹran lati maa ṣe awon ohun akinkanju, mo si fẹran irinajo to le.'' ''Mo ti gun ori apata Kilimanjaro ri, eyii to jẹ ori apata to ga julọ nilẹ Afrika.'' ''Bakan naa ni mo ti wa alupupu lati Naijiria lọ si orilẹ-ede Ghana ri, ti mo tun gun alupupu pada wa si Naijiria.'' ''Nigba ti mo pinnu lati rin irinajo yii lati ilu London si Naijiria, mo woye pe bawo ni mo ṣe le ṣe lati fi tu awọn eeyan lọrun ki n si fi ṣe awọn araalu loore.'' O ni yatọ si pe oun fẹran awọn irinajo to le, oun tun gunle irinajo naa lati ṣe ikowojọ fun awọn alaini, ati lati fi gbogun ti aisan to n ba awọn eeyan finra bii polio. Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 yii ni Adeyanju gbera kuro niluu London pẹlu alupupu rẹ, ti ireti ṣi wa pe yoo gunlẹ si Naijiria lọjọ Isinmi, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2022. | https://www.bbc.com/yoruba/media-61623688 |
2health
| coronavirus: Ìdí tí obìnrin fi leè rù ú là ju ọkùnrin lọ | O n dabi ẹni pe o ṣeeṣe fun ọkunrin lati ku lọwọ arun Coronavirus to n ja nilẹ bayii ju awọn ọkunrin lọ. Bakan naa si ni ko ṣeeṣe fawọn ọmọde lati ku nipasẹ arun naa to bi awọn agba lọ. Ọpọlọpọ awọn eeyan lo jẹ wi pe arun yii yoo kan ṣi ni fila lọ ni, ṣugbọn awọn miran a maa tipasẹ arun yii dero ọrun. Ti o ba ri bẹẹ, ki wa gan an lo n fa iyatọ laarin bi ọṣẹ arun yii ṣe le si laarin ẹya akọ atabo tabi ara awọn ọmọ wẹwẹ ati agbalagba? Gbogbo awọn iroyin ti a ri kojọ lori eyi wa latawọn iwadii gbankọ gbi tawọn ibudo amojuto ajakalẹ arun lorilẹede China ṣe, Chinese Centers of Disease Control. ẹgbẹrun mẹrinlelogoji (44,000) ni iwadii naa gbe yẹwo ninu eyi to ti fihan pe ida mẹta din diẹ ninu ọgọrun (2.8%) awọn ọkunrin to ko arun Coronavirus yii lo jade laye; bẹẹni ida meji o din diẹ ninu ọgọrun (1.7%) awọn obirin to ko arun naa lo jade laye. Bẹẹni ko tilẹ sun mọ ida kan ninu ọgọrun (0.2%) awọn ọmọde ati ọṣọrọ ọdọ to ko arun yii to jade laye; nigba ti ida marundinlogun (15%) awọn agbalagba ti ọjọ ori wọn ti ju ọgọrin ọdun lọ laisan Coronavirus ti ran lọ sọrun. Ọna meji ni a le gba ṣalaye abajade iwadii naa lori eyii. Yala ko jẹ wi pe awọn obirin atọmọde ko lee saba ko arun yii tabi ko jẹ wi pe awọn ẹya ara wọn lagbara lati koju kokoro arun coronavirus ọhun. 'Koko pataki kan ni wi pe, kokoro arun tuntun yii n tan kalẹ, gbogbo eeyan lo si lee ko o." Eyi jẹ ọrọ Dokita Bharat Pankhania lati fasiti Exeter sọ. Idi eyi ni pe ko si ajẹsara kankan ninu agọ ara to lee dena arun yii nitori ko si ẹnu to lugbadi rẹ ṣaaju asiko yii ri. Lootọ o, lasiko ti arun naa ṣẹṣẹ bẹẹ, o ṣoro diẹ fun awọn ọmọde lati ko kokoro arun naa. Yoo ya ọ lẹnu pe iyatọ gedegbe wa laarin iye awọn ọkunrin ati obinrin to n ku nipasẹ arun yii? Ṣugbọn eyi ko ya awọn onimọ sayẹnsi lẹnu o. Bi a ko ba ni jayopa, bakan naa lọrọ ṣe rilawọn aisan miran bii otutu. Lara idahun si eyi naa ni pe, igbe aye awọn ọkunrin buru jai ju tawọn obirin lọ lawọn nnkan ti wọn n ṣe bii siga mimu. "Siga n ba ẹdọ jẹ. Iru ẹni bẹẹ ko lee yee rara." Gẹgẹ bi Dokita Nathalie MacDermott lati ile ẹkọ giga Kings College ni ilu London ṣe sọ. Eyi ṣeeṣe ko fa wahala nla lorilẹede China nibi ti iwadii ti fihan pe nnkan bi ida mejilelaadọta ninu ọgọrun awọn ọkunrin wọn lo n ṣana si siga ti o si jẹ pe iwọn perete ida mẹta nini ọgọrun awọn obinrin lo n mu siga nibẹ. Bakan naa ni iwadii fihan pe iyatọ wa laarin eroja ajẹsara abawaye awọn obinrin ati ti ọkunrin ati ọna ti awọn eroja ajẹsara yii maa fi n gbera sọ nigbakugba ti aisan tabi arun kan ba fẹ dide. Làá hàn mí dé, ètò tó ń ṣàlàyé ohun tó yẹ ká ṣe láti dènà àrùn Coronavirus Mi o tíì rí olórí tó fẹ́ràn Naijiria tó Baba Obasanjo- Yoruba Council of Elders Idahun awọn ọjọgbọn ni pe 'rara'ṣugbọn awọn akọṣẹmọṣẹ kan ti n sọ ọ wi pe o ṣeeṣe o ki ọrọ maa ri bẹẹ Oriṣiriṣi nnkan ni oyun nini maa n ṣe fun ara, lara rẹ si ni dindin agbara awọn eroja ajẹsara ara ku. Eyi si maa n mu ki wọn wa larọwọto ọpọlọpọ kokoro arun lasiko oyun yii. Ijọba ilẹ Gẹẹsi ni 'ko si ami kan gboogi' to fihan pe awọn obirin to ba loyun lee fara kaasa arun coronavirus ju awọn ti ko loyun lọ. Awọn ọmọde lee ko arun Coronavirus. Iroyin tilẹ ti fi idi rẹ mulẹ pe ninu awọn to ti ni arun Ccoronavirus lagbaye bayii, ọmọ kekere jojolo ti wọn ṣẹṣẹ bi wa lara wọn. Iyatọ nla wa laarin ilana eroja ajẹsara amuwaye (immune system) ọmọde ati ti agbalagba. Awọn eroja yii lara awọn ọmọde maa n ṣiṣẹ ni kiakia ni; wọn a si maa jẹ iṣẹ kọja ibi ti wọn ba ran wọn de nigba miran. Eleyii lo maa n faa tawọn ọmọde maa fi n saba n ni aisan iba. Bi awọn eroja yii ba n jẹ iṣẹ kọja ala, wọn le ṣe akoba fun awọn eroja ara yoku, ara idi si niyi ti awọn arun coronavirus lee mu iku dani. Amọṣa gẹgẹ bi Dokita MacDermott ṣe sọ, eyi kii waye pẹlu arun Coronavirus lara awọn ọmọde o, ko si si ẹni to mọ ohun ti arun naa n ṣe lara awọn ọmọde ti eyi fi ri bẹẹ. | coronavirus: Ìdí tí obìnrin fi leè rù ú là ju ọkùnrin lọ O n dabi ẹni pe o ṣeeṣe fun ọkunrin lati ku lọwọ arun Coronavirus to n ja nilẹ bayii ju awọn ọkunrin lọ. Bakan naa si ni ko ṣeeṣe fawọn ọmọde lati ku nipasẹ arun naa to bi awọn agba lọ. Ọpọlọpọ awọn eeyan lo jẹ wi pe arun yii yoo kan ṣi ni fila lọ ni, ṣugbọn awọn miran a maa tipasẹ arun yii dero ọrun. Ti o ba ri bẹẹ, ki wa gan an lo n fa iyatọ laarin bi ọṣẹ arun yii ṣe le si laarin ẹya akọ atabo tabi ara awọn ọmọ wẹwẹ ati agbalagba? Gbogbo awọn iroyin ti a ri kojọ lori eyi wa latawọn iwadii gbankọ gbi tawọn ibudo amojuto ajakalẹ arun lorilẹede China ṣe, Chinese Centers of Disease Control. ẹgbẹrun mẹrinlelogoji (44,000) ni iwadii naa gbe yẹwo ninu eyi to ti fihan pe ida mẹta din diẹ ninu ọgọrun (2.8%) awọn ọkunrin to ko arun Coronavirus yii lo jade laye; bẹẹni ida meji o din diẹ ninu ọgọrun (1.7%) awọn obirin to ko arun naa lo jade laye. Bẹẹni ko tilẹ sun mọ ida kan ninu ọgọrun (0.2%) awọn ọmọde ati ọṣọrọ ọdọ to ko arun yii to jade laye; nigba ti ida marundinlogun (15%) awọn agbalagba ti ọjọ ori wọn ti ju ọgọrin ọdun lọ laisan Coronavirus ti ran lọ sọrun. Ọna meji ni a le gba ṣalaye abajade iwadii naa lori eyii. Yala ko jẹ wi pe awọn obirin atọmọde ko lee saba ko arun yii tabi ko jẹ wi pe awọn ẹya ara wọn lagbara lati koju kokoro arun coronavirus ọhun. 'Koko pataki kan ni wi pe, kokoro arun tuntun yii n tan kalẹ, gbogbo eeyan lo si lee ko o." Eyi jẹ ọrọ Dokita Bharat Pankhania lati fasiti Exeter sọ. Idi eyi ni pe ko si ajẹsara kankan ninu agọ ara to lee dena arun yii nitori ko si ẹnu to lugbadi rẹ ṣaaju asiko yii ri. Lootọ o, lasiko ti arun naa ṣẹṣẹ bẹẹ, o ṣoro diẹ fun awọn ọmọde lati ko kokoro arun naa. Yoo ya ọ lẹnu pe iyatọ gedegbe wa laarin iye awọn ọkunrin ati obinrin to n ku nipasẹ arun yii? Ṣugbọn eyi ko ya awọn onimọ sayẹnsi lẹnu o. Bi a ko ba ni jayopa, bakan naa lọrọ ṣe rilawọn aisan miran bii otutu. Lara idahun si eyi naa ni pe, igbe aye awọn ọkunrin buru jai ju tawọn obirin lọ lawọn nnkan ti wọn n ṣe bii siga mimu. "Siga n ba ẹdọ jẹ. Iru ẹni bẹẹ ko lee yee rara." Gẹgẹ bi Dokita Nathalie MacDermott lati ile ẹkọ giga Kings College ni ilu London ṣe sọ. Eyi ṣeeṣe ko fa wahala nla lorilẹede China nibi ti iwadii ti fihan pe nnkan bi ida mejilelaadọta ninu ọgọrun awọn ọkunrin wọn lo n ṣana si siga ti o si jẹ pe iwọn perete ida mẹta nini ọgọrun awọn obinrin lo n mu siga nibẹ. Bakan naa ni iwadii fihan pe iyatọ wa laarin eroja ajẹsara abawaye awọn obinrin ati ti ọkunrin ati ọna ti awọn eroja ajẹsara yii maa fi n gbera sọ nigbakugba ti aisan tabi arun kan ba fẹ dide. Làá hàn mí dé, ètò tó ń ṣàlàyé ohun tó yẹ ká ṣe láti dènà àrùn Coronavirus Mi o tíì rí olórí tó fẹ́ràn Naijiria tó Baba Obasanjo- Yoruba Council of Elders Idahun awọn ọjọgbọn ni pe 'rara'ṣugbọn awọn akọṣẹmọṣẹ kan ti n sọ ọ wi pe o ṣeeṣe o ki ọrọ maa ri bẹẹ Oriṣiriṣi nnkan ni oyun nini maa n ṣe fun ara, lara rẹ si ni dindin agbara awọn eroja ajẹsara ara ku. Eyi si maa n mu ki wọn wa larọwọto ọpọlọpọ kokoro arun lasiko oyun yii. Ijọba ilẹ Gẹẹsi ni 'ko si ami kan gboogi' to fihan pe awọn obirin to ba loyun lee fara kaasa arun coronavirus ju awọn ti ko loyun lọ. Awọn ọmọde lee ko arun Coronavirus. Iroyin tilẹ ti fi idi rẹ mulẹ pe ninu awọn to ti ni arun Ccoronavirus lagbaye bayii, ọmọ kekere jojolo ti wọn ṣẹṣẹ bi wa lara wọn. Iyatọ nla wa laarin ilana eroja ajẹsara amuwaye (immune system) ọmọde ati ti agbalagba. Awọn eroja yii lara awọn ọmọde maa n ṣiṣẹ ni kiakia ni; wọn a si maa jẹ iṣẹ kọja ibi ti wọn ba ran wọn de nigba miran. Eleyii lo maa n faa tawọn ọmọde maa fi n saba n ni aisan iba. Bi awọn eroja yii ba n jẹ iṣẹ kọja ala, wọn le ṣe akoba fun awọn eroja ara yoku, ara idi si niyi ti awọn arun coronavirus lee mu iku dani. Amọṣa gẹgẹ bi Dokita MacDermott ṣe sọ, eyi kii waye pẹlu arun Coronavirus lara awọn ọmọde o, ko si si ẹni to mọ ohun ti arun naa n ṣe lara awọn ọmọde ti eyi fi ri bẹẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51788497 |
2health
| Anti-vaccine mandate protests: Canada ṣetán láti gbẹ́sẹ̀ lé àkáùntì àwọn tó ń ṣẹ ìwọ́de táko abẹ́rẹ́ covid-19 | Olootu ijọba orilẹede Canada, Justin Trudeau ti kede pe ijọba yoo gbẹsẹ le akaunti gbogbo awọn to n ṣe iwọde tako gbigba abẹrẹ ajẹsara covid-19. Trudeau ṣalaye pe awọn ile ifopamọ le gbẹsẹ le akaunti awọn to ba ni ohun kan ṣe pẹlu iwọde tako abẹrẹ covid-19. Ọgọọrọ awọn olouwọde ni wọn ti n fi ẹhonu han tako gbigba abẹrẹ coronavirus. Awọn agbofinro lo tu awọn oluwọde naa ka ni Windsor lọjọ Aiku to kọja. Iwọde to bẹrẹ lati tako ikede ijọba pe gbogbo awọn to wa ọkọ akẹru nla ti wọn n gba ibode Canada ati Amẹrika kọja gbọdọ gba abẹrẹ covid-19. Amọ ifẹhonuhan naa ti di ohun ti wọn n fi tako gbogbo eto ijọba lati dẹna coronavirus bayii. Trudeau ni ''igbesẹ yii wa lati ri pe awọn eeyan Canada ko si ninu ewu. Bakan naa ni a tun n ṣe eleyii lati daabo bo iṣẹ awọn eeyan ni Canada.'' Olootu ijọba ilẹ Canada ni ijọba yoo fawọn ọlọpaa ni irinṣẹ ti wọn nilo lati ju awọn oluwọde si atimọle ati lati daabo bo ohun amayedẹrun. Ọpọ koro oju si Trudeau lori igbesẹ rẹ lẹyin ti wọn lo ṣe atilẹyin fawọn agbẹ ti wọn di ọna mọrosẹ ni India lọdun 2021 lasiko ti wọn n ṣe iwọde. Wọn ni Trudeau lo fẹnu ara rẹ sọ pe Canada ko le ṣalai ṣe atilẹyin fawọn to n ba ṣe iwọde wọọrọwọ. Igbakeji olootu ijọba Canada naa, Chrystia Freeland sọ pe awọn banki le gbẹsẹ le akaunti ẹnikẹni to ba kopa ninu ifẹhonuhan ọhun. Freeland fikun ọrọ rẹ pe iwe adojutofo ọkọ ẹnikẹni to ba ni ohun kan ṣe pẹlu iwọde naa le ni idaduro fun igba diẹ. Freeland ni ijọba n lo eleyii lati mọ awọn to n pese owo fawọn oluwode. O sọrọ yii lẹyin tawọn onijibi ori ayelujara sọ pe eeyan ẹgbẹrun lọna mẹtalelaadọrun lo ṣe irawọn owo to le ni miliọnu mẹjo ($8.4m) fawọn awakọ nla akẹru. | Anti-vaccine mandate protests: Canada ṣetán láti gbẹ́sẹ̀ lé àkáùntì àwọn tó ń ṣẹ ìwọ́de táko abẹ́rẹ́ covid-19 Olootu ijọba orilẹede Canada, Justin Trudeau ti kede pe ijọba yoo gbẹsẹ le akaunti gbogbo awọn to n ṣe iwọde tako gbigba abẹrẹ ajẹsara covid-19. Trudeau ṣalaye pe awọn ile ifopamọ le gbẹsẹ le akaunti awọn to ba ni ohun kan ṣe pẹlu iwọde tako abẹrẹ covid-19. Ọgọọrọ awọn olouwọde ni wọn ti n fi ẹhonu han tako gbigba abẹrẹ coronavirus. Awọn agbofinro lo tu awọn oluwọde naa ka ni Windsor lọjọ Aiku to kọja. Iwọde to bẹrẹ lati tako ikede ijọba pe gbogbo awọn to wa ọkọ akẹru nla ti wọn n gba ibode Canada ati Amẹrika kọja gbọdọ gba abẹrẹ covid-19. Amọ ifẹhonuhan naa ti di ohun ti wọn n fi tako gbogbo eto ijọba lati dẹna coronavirus bayii. Trudeau ni ''igbesẹ yii wa lati ri pe awọn eeyan Canada ko si ninu ewu. Bakan naa ni a tun n ṣe eleyii lati daabo bo iṣẹ awọn eeyan ni Canada.'' Olootu ijọba ilẹ Canada ni ijọba yoo fawọn ọlọpaa ni irinṣẹ ti wọn nilo lati ju awọn oluwọde si atimọle ati lati daabo bo ohun amayedẹrun. Ọpọ koro oju si Trudeau lori igbesẹ rẹ lẹyin ti wọn lo ṣe atilẹyin fawọn agbẹ ti wọn di ọna mọrosẹ ni India lọdun 2021 lasiko ti wọn n ṣe iwọde. Wọn ni Trudeau lo fẹnu ara rẹ sọ pe Canada ko le ṣalai ṣe atilẹyin fawọn to n ba ṣe iwọde wọọrọwọ. Igbakeji olootu ijọba Canada naa, Chrystia Freeland sọ pe awọn banki le gbẹsẹ le akaunti ẹnikẹni to ba kopa ninu ifẹhonuhan ọhun. Freeland fikun ọrọ rẹ pe iwe adojutofo ọkọ ẹnikẹni to ba ni ohun kan ṣe pẹlu iwọde naa le ni idaduro fun igba diẹ. Freeland ni ijọba n lo eleyii lati mọ awọn to n pese owo fawọn oluwode. O sọrọ yii lẹyin tawọn onijibi ori ayelujara sọ pe eeyan ẹgbẹrun lọna mẹtalelaadọrun lo ṣe irawọn owo to le ni miliọnu mẹjo ($8.4m) fawọn awakọ nla akẹru. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60391949 |
4religion
| Kí ni ìdí ariwo lórí bí Tinubu ṣe yan Musulumi gẹ́gẹ́ bíi igbákejì Ààrẹ? - CAN dáhùn | Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorilẹede Naijiria ti ni awọn ko pa ohun wọn da lori titako ki ẹsin kan naa dije du ipo aarẹ lorilẹede Naijiria. Agbẹnusọ ẹgbẹ CAN, Pasitọ Adebayo Oladeji lo sọ bẹẹ lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iyansipo gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ, Kashim Shettima gẹgẹ bi igbakeji oludije lẹgbẹ oṣelu APC. Oladeji ni ki awọn eniyan ma sọrọ nipa asiko MKO Abiola nitori aye dara nigba naa ju asiko yii lọ. ‘’Ko si didara ti oludije to ba yan Musulumi gẹgẹ bi igbakeji yoo ṣe fun wa.’’ ‘’Ki wọn lọ wọ iwe ofin Naijiria lẹyin ogun abẹlẹ, o yẹ ki wọn ṣe didara si gbogbo ẹya ati ẹsin ni Naijiria’’. ‘’Nigba Abiola ko si Boko Haram to n pa awọn Kristeni, to n jo ṣọṣi abi awọn agbebọn to n ji pasitọ gbe ti wọn si n gba ọkọ awọn eniyan lọwọ wọn.’’ Yiyan igbakeji ẹlẹsin kan naa fihan pe wọn ko naani awa ẹlẹsin Kristẹni ni Naijiria. Amọ wọn fikun un pe ko si ohun ti awọn le ṣe sii yatọ si ki awọn ọmọ Naijiria dibo fun ẹni ti ọkan wọn ba fẹ ni idibo ọ̀dun to n bọ. Ajafẹtọ ọmọ Naijiria, Aisha Yesufu ni yiyan igbakeji lati inu ẹsin kan naa ko bojumu, awọn ọmọ Naijiria ko si ni gba iru rẹ. Ninu ọrọ tirẹ, Ajafẹtọ awọn ọdọ Rinu Oduala ni kii ṣe pe ọrọ ẹlẹsin kan naa lo wa nilẹ bayii, amọ ohun ti awọn eniyan n bere fun ni ki pinpin ẹtọ ọmọniyan dọgba lorilẹede Naijiria. Amọ agbẹjọro Agba lorilẹeede Naijiria, Festus Keyamo ni oun faramọ ohun ti Tinubu ṣe lori ọrọ igbakeji. Keyamo ni ko si orilẹede kankan ni agbaye to jẹ pe idagbasoke niiṣe pẹlu didọgba awọn ẹlẹsin to wa ni orilẹede naa. O ni ṣiṣe ijọba fun idagbasoke kii ṣe lati gboriyin fun awọn adari ẹsin kan tabi jẹ ki nkan lọ bi wọn ṣe fẹ. | Kí ni ìdí ariwo lórí bí Tinubu ṣe yan Musulumi gẹ́gẹ́ bíi igbákejì Ààrẹ? - CAN dáhùn Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorilẹede Naijiria ti ni awọn ko pa ohun wọn da lori titako ki ẹsin kan naa dije du ipo aarẹ lorilẹede Naijiria. Agbẹnusọ ẹgbẹ CAN, Pasitọ Adebayo Oladeji lo sọ bẹẹ lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iyansipo gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ, Kashim Shettima gẹgẹ bi igbakeji oludije lẹgbẹ oṣelu APC. Oladeji ni ki awọn eniyan ma sọrọ nipa asiko MKO Abiola nitori aye dara nigba naa ju asiko yii lọ. ‘’Ko si didara ti oludije to ba yan Musulumi gẹgẹ bi igbakeji yoo ṣe fun wa.’’ ‘’Ki wọn lọ wọ iwe ofin Naijiria lẹyin ogun abẹlẹ, o yẹ ki wọn ṣe didara si gbogbo ẹya ati ẹsin ni Naijiria’’. ‘’Nigba Abiola ko si Boko Haram to n pa awọn Kristeni, to n jo ṣọṣi abi awọn agbebọn to n ji pasitọ gbe ti wọn si n gba ọkọ awọn eniyan lọwọ wọn.’’ Yiyan igbakeji ẹlẹsin kan naa fihan pe wọn ko naani awa ẹlẹsin Kristẹni ni Naijiria. Amọ wọn fikun un pe ko si ohun ti awọn le ṣe sii yatọ si ki awọn ọmọ Naijiria dibo fun ẹni ti ọkan wọn ba fẹ ni idibo ọ̀dun to n bọ. Ajafẹtọ ọmọ Naijiria, Aisha Yesufu ni yiyan igbakeji lati inu ẹsin kan naa ko bojumu, awọn ọmọ Naijiria ko si ni gba iru rẹ. Ninu ọrọ tirẹ, Ajafẹtọ awọn ọdọ Rinu Oduala ni kii ṣe pe ọrọ ẹlẹsin kan naa lo wa nilẹ bayii, amọ ohun ti awọn eniyan n bere fun ni ki pinpin ẹtọ ọmọniyan dọgba lorilẹede Naijiria. Amọ agbẹjọro Agba lorilẹeede Naijiria, Festus Keyamo ni oun faramọ ohun ti Tinubu ṣe lori ọrọ igbakeji. Keyamo ni ko si orilẹede kankan ni agbaye to jẹ pe idagbasoke niiṣe pẹlu didọgba awọn ẹlẹsin to wa ni orilẹede naa. O ni ṣiṣe ijọba fun idagbasoke kii ṣe lati gboriyin fun awọn adari ẹsin kan tabi jẹ ki nkan lọ bi wọn ṣe fẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cd1kww137e6o |
1entertainment
| Burna Boy yí ìpinnu padà, yóò kópa ní àjọ̀dún orin lórílẹ̀-èdè South Áfríkà | Gbajugbaja olorin takasufe ọmọ Naijiria Burna Boy ti ni oun yoo jọwọ lara owo tawọn ba pa nibi ode orin ti yoo waye lorileede South Africa fawọn to farakasa Xenophobia. Loju opo Twitter rẹ ni akọrin yii ti fi ọrọ naa hande. Ṣaaju asiko yii, Burna Boy ti leri pe oun ko ni fẹsẹ tẹ ilẹ South Afrika nitori idẹyẹsi sawọn ọmọ ilẹ Afrika mIiran to n waye nibẹ. Ajọdun orin ti o fẹ kopa yii ni yoo jẹ igba akọkọ ti Burna Boy yoo tẹ South Afrika lati ọdun 2017. Lara awọn ti wọn yoo jijọ fi orin bẹnu atẹ lu idẹyẹsi awọn eeyan ilẹ miran ní South Afrika la ti ri awọn akọrin bi Kwesta Jidenna ati Busiswa. Akori ajọdun orin naa ti yoo waye lọjọ kẹtalelogun oṣu Kọkanla ni ''Afirika, pawọ pọ'' | Burna Boy yí ìpinnu padà, yóò kópa ní àjọ̀dún orin lórílẹ̀-èdè South Áfríkà Gbajugbaja olorin takasufe ọmọ Naijiria Burna Boy ti ni oun yoo jọwọ lara owo tawọn ba pa nibi ode orin ti yoo waye lorileede South Africa fawọn to farakasa Xenophobia. Loju opo Twitter rẹ ni akọrin yii ti fi ọrọ naa hande. Ṣaaju asiko yii, Burna Boy ti leri pe oun ko ni fẹsẹ tẹ ilẹ South Afrika nitori idẹyẹsi sawọn ọmọ ilẹ Afrika mIiran to n waye nibẹ. Ajọdun orin ti o fẹ kopa yii ni yoo jẹ igba akọkọ ti Burna Boy yoo tẹ South Afrika lati ọdun 2017. Lara awọn ti wọn yoo jijọ fi orin bẹnu atẹ lu idẹyẹsi awọn eeyan ilẹ miran ní South Afrika la ti ri awọn akọrin bi Kwesta Jidenna ati Busiswa. Akori ajọdun orin naa ti yoo waye lọjọ kẹtalelogun oṣu Kọkanla ni ''Afirika, pawọ pọ'' | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-50378516 |
2health
| Baby Placenta: Ṣé lóòtọ́ọ́ làwọn kan máa ń fi ibi ọmọ ṣe oògùn? | Yoruba ni tibi-tire la wale aye, tibi-tire la se ẹda eeyan, bi aye ire se wa, naa ni aye ibi se wa. Ni ọjọ ti obinrin ba ti kunlẹ bimọ, ti ọmọ jade eyi tii se ire, naa ni olubi ọmọ yoo jade, eyi ti wọn tun n pe ni ibi ọmọ tabi Placenta ni ede oyinbo. Ni aye atijọ, olubi ọmọ yii se pataki fun ibi ọmọ, baba to ba si gba olubi ọmọ tabi sin bo se yẹ, ni asa Yoruba mọ bii baba ọmọ. Baba ọmọ lo maa n gbe olubi ọmọ ni kere ti ọmọ ba ti bọ lara iya ọmọ tan. Olubi ọmọ tawọn kan maa n pe ni ibi ọmọ jẹ ohun to ṣe pataki laarin oriṣiiriṣii ẹya lorilẹ-ede Naijiria. Ko si ọmọ ti kii ni olubi, nitori ohun gan ni atẹle to n ba ọmọ wa sile aye. Sugbọn oniruuru ọrọ ni awọn eeyan maa n sọ nipa pataki olubi ọmọ, eyi to yẹ ki olukaluku mọ boya o tọ abi ko tọ. Dokita Joseph Akinde, to jẹ onimọ nipa itọju awọn alaboyun ṣalaye pe igbagbọ wa ninu aṣa ibilẹ lasan, ni ohun ti ọpọ eeyan maa n sọ nipa olubi ọmọ. Dokita Akinde sọ pe awọn kan tiẹ ni igbagbọ awọn eeyan kan wipe ibi ọmọ ni ohun ṣe pẹlu ayanmọ ọmọ naa laye. Akinde salaye pe ''Igbagbọ awọn eeyan ni pe ohunkohun ti ẹnikẹni ba ṣe pẹlu ibi ọmọ ni nnkan ṣe pẹlu ohun ti ọmọ naa yoo da laye. Ṣugbọn a ko le fidi eleyi mulẹ ninu iṣẹ iṣegun tabi ninu imọ ijinlẹ sayẹnsi, igbagbọ ninu aṣa lasan ni,'' Dokita Akinde ṣalaye. Amọ dokita onimọ nipa itọju obinrin naa sọ pe, dokita ti ko ri ibi ọmọ gbe fun baba ọmọ ti wọ gau. Wọn ni ọpọ awọn dokita ni wọn ti dunkoko mọ lori ibi ọmọ, koda wọn sọ pe awọn eeyan maa n gbe dokita lọ si ileẹjọ lori órọ ibi ọmọ. Amọ, Dokita Akinde ṣalaye pe aṣa lasan an ni gbogbo rẹ, ko ni ohun kan ṣe pẹlu sayẹnsi. Wo igbagbọ awọn eeyan lori olubi ọmọ, ti wọn se maa n fẹ gba a nile iwosan: Nigba to n salaye oniruuru ọna ti awọn eeyan fi ni igbagbọ ọtọọtọ si pataki ohun ti ibi ọmọ jẹ, Dokita Oyede tun sọ iriri rẹ lori bi awn obi se n lakaka lati gba ibi ọmọ kuro nile iwosan. ''Awọn eeyan kan maa n bo olubi ọmọ mọlẹ, igbagbọ wọn ni pe ibikibi ti ọmọ naa ba wa, o gbọdọ de ibi ti wọn ri ibi rẹ mọ lọjọ kan. Awọn mii tun gbagbọ pe wọn maa n fi olubi ọmọ ṣe oogun, idi niyii ti wọn maa fi n gbaa lati ile iwosan. Mo ranti ni bii ọdun diẹ sẹyin bi ẹbi obinrin kan to bimọ si ile iwosan ijọba ṣe dunkoko mọ dotika to gbẹbi fun obinrin naa nitori ko mọ ibi ti ibi ọmọ wa. Niṣe lawọn ẹbi naa lọ sọ fawọn akọroyin pe dokita naa ti ta olubi ọmọ awọn, o si ti ta ayanmọ rẹ laye,'' Dokita Akinde lo sọ bẹẹ. Alaga ẹgbẹ awọn dokita oniṣegun oyinbo nipinlẹ Cross River, Dokita Innocent Abang naa kin ọrọ Ọgbẹni Akinde lẹyin. Dokita Abang ni ọpọ lo gbagbọ pe ibi ti wọn ba ri ibi ọmọ si ni ayanmọ rẹ wa. Dokita sọ pe awọn tiẹ maa n gbin igi agbọn sori ibi ti wọn ba ri ibi ọmọ si, ''wọn gbagbọ pe bi igi naa ṣe n dagba ni ọmọ naa yoo maa dagba.'' | Baby Placenta: Ṣé lóòtọ́ọ́ làwọn kan máa ń fi ibi ọmọ ṣe oògùn? Yoruba ni tibi-tire la wale aye, tibi-tire la se ẹda eeyan, bi aye ire se wa, naa ni aye ibi se wa. Ni ọjọ ti obinrin ba ti kunlẹ bimọ, ti ọmọ jade eyi tii se ire, naa ni olubi ọmọ yoo jade, eyi ti wọn tun n pe ni ibi ọmọ tabi Placenta ni ede oyinbo. Ni aye atijọ, olubi ọmọ yii se pataki fun ibi ọmọ, baba to ba si gba olubi ọmọ tabi sin bo se yẹ, ni asa Yoruba mọ bii baba ọmọ. Baba ọmọ lo maa n gbe olubi ọmọ ni kere ti ọmọ ba ti bọ lara iya ọmọ tan. Olubi ọmọ tawọn kan maa n pe ni ibi ọmọ jẹ ohun to ṣe pataki laarin oriṣiiriṣii ẹya lorilẹ-ede Naijiria. Ko si ọmọ ti kii ni olubi, nitori ohun gan ni atẹle to n ba ọmọ wa sile aye. Sugbọn oniruuru ọrọ ni awọn eeyan maa n sọ nipa pataki olubi ọmọ, eyi to yẹ ki olukaluku mọ boya o tọ abi ko tọ. Dokita Joseph Akinde, to jẹ onimọ nipa itọju awọn alaboyun ṣalaye pe igbagbọ wa ninu aṣa ibilẹ lasan, ni ohun ti ọpọ eeyan maa n sọ nipa olubi ọmọ. Dokita Akinde sọ pe awọn kan tiẹ ni igbagbọ awọn eeyan kan wipe ibi ọmọ ni ohun ṣe pẹlu ayanmọ ọmọ naa laye. Akinde salaye pe ''Igbagbọ awọn eeyan ni pe ohunkohun ti ẹnikẹni ba ṣe pẹlu ibi ọmọ ni nnkan ṣe pẹlu ohun ti ọmọ naa yoo da laye. Ṣugbọn a ko le fidi eleyi mulẹ ninu iṣẹ iṣegun tabi ninu imọ ijinlẹ sayẹnsi, igbagbọ ninu aṣa lasan ni,'' Dokita Akinde ṣalaye. Amọ dokita onimọ nipa itọju obinrin naa sọ pe, dokita ti ko ri ibi ọmọ gbe fun baba ọmọ ti wọ gau. Wọn ni ọpọ awọn dokita ni wọn ti dunkoko mọ lori ibi ọmọ, koda wọn sọ pe awọn eeyan maa n gbe dokita lọ si ileẹjọ lori órọ ibi ọmọ. Amọ, Dokita Akinde ṣalaye pe aṣa lasan an ni gbogbo rẹ, ko ni ohun kan ṣe pẹlu sayẹnsi. Wo igbagbọ awọn eeyan lori olubi ọmọ, ti wọn se maa n fẹ gba a nile iwosan: Nigba to n salaye oniruuru ọna ti awọn eeyan fi ni igbagbọ ọtọọtọ si pataki ohun ti ibi ọmọ jẹ, Dokita Oyede tun sọ iriri rẹ lori bi awn obi se n lakaka lati gba ibi ọmọ kuro nile iwosan. ''Awọn eeyan kan maa n bo olubi ọmọ mọlẹ, igbagbọ wọn ni pe ibikibi ti ọmọ naa ba wa, o gbọdọ de ibi ti wọn ri ibi rẹ mọ lọjọ kan. Awọn mii tun gbagbọ pe wọn maa n fi olubi ọmọ ṣe oogun, idi niyii ti wọn maa fi n gbaa lati ile iwosan. Mo ranti ni bii ọdun diẹ sẹyin bi ẹbi obinrin kan to bimọ si ile iwosan ijọba ṣe dunkoko mọ dotika to gbẹbi fun obinrin naa nitori ko mọ ibi ti ibi ọmọ wa. Niṣe lawọn ẹbi naa lọ sọ fawọn akọroyin pe dokita naa ti ta olubi ọmọ awọn, o si ti ta ayanmọ rẹ laye,'' Dokita Akinde lo sọ bẹẹ. Alaga ẹgbẹ awọn dokita oniṣegun oyinbo nipinlẹ Cross River, Dokita Innocent Abang naa kin ọrọ Ọgbẹni Akinde lẹyin. Dokita Abang ni ọpọ lo gbagbọ pe ibi ti wọn ba ri ibi ọmọ si ni ayanmọ rẹ wa. Dokita sọ pe awọn tiẹ maa n gbin igi agbọn sori ibi ti wọn ba ri ibi ọmọ si, ''wọn gbagbọ pe bi igi naa ṣe n dagba ni ọmọ naa yoo maa dagba.'' | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-56834292 |
3politics
| Ibi tí Yorùbá ńfẹ́ kọ́ ni Adebanjo kọjú sí, ẹ̀yìn Tinubu ni Afenifere tò sí -Wale Oshun | Aṣiwaju ẹgbẹ ọmọbibi ilẹ Yoruba, Afenifere Renewal Group, Ọgbẹni Olawalu Oshun, ti sọ pe Bọla Tinubu lawọn n ṣe atilẹyin fun, kii ṣe Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party. Ṣaaju ni olori Afenifere, Oloye Ayo Adebanjo sọ nibi eto kan lọjọ Aje pe Obi ni ẹgbẹ naa n tilẹyin. Ọgbẹni Oshun sọ fun BBC pe ohun ti Ẹgbẹ Afẹnifẹre Renewal Group duro ti ni ifẹ ọmọ Yoruba nile ati lẹyin odi, ti o si da awon loju pe ohun to ọgọrọ ọmọ Yoruba n fẹ naa ni ki ọmọ Yoruba to kun oju oṣuwọn o wọle sipo aarẹ. O ni kii ṣe pe ẹgbẹ naa ko ni igbagbọ ninu iṣọkan Naijiria, ati wi pe boya awọn eeyan lati ẹya miran ko ni jade. “Ohun to fa ipinnu wa lati duro ti ọmọ Yoruba laarin awọn to n dije bayii ko ju wi pe, oun lo kun oju oṣuwọn julọ ninu gbogbo oludije fun ipo aarẹ. Ọgbẹni Oshun ni Bola Tinubu, ni awọn rii pe yoo lee yanju awọn ipenija ti o n doju kọ ọmọ Naijiria, leyi ti awọn si ti n fọnrere rẹ ṣaaju akoko yii. Ọrọ ti Afẹnifere sọ yii n fidi ohun ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ipolongo ibo Bola Tinubu, Bayọ Ọnanuga sọ pe ọrọ ara oloye Adebanjọ lo n sọkii ṣe ohun ti ẹgbẹ Afẹnifẹre n fe. Asiwaju ẹgbẹ Yoruba kan ti a mọ si Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjọ ti ṣalaye idi ti ẹgbẹ naa ko fi fẹ ti oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu tabi ti PDP Atiku Abubakar lẹyin fun ibo aarẹ Naijiria ti yoo waye lọdun 2023. Asiwaju ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjọ ṣalaye nibi apero kan to ṣe pẹl’awọn akọroyin pe iṣọkan ati ilana aparo kan ko ga ju ọkan lọ pẹlu idajọ ododo lti ẹgbẹ naa duro fun lo mu ko pinnu eyi. Adebanjọ n fi apero naa fesi si ọrọ ti ileeṣẹ ipolongo idibo aarẹ fun Bola Ahmed Tinubu fi sita laipẹ yii ni ninu eyi to ti sọ ọ di mimọ pe iṣẹ ara oloye Adebanjọ lo n jẹ o ko jẹ iṣẹ ọmọ Yoruba lori Peter Obi to gbe ka ori. Oludari eto ipolongo fun ileesẹ ipolongo ibo fun Bola Tinubu, Bayọ Ọnanuga ṣalaye bu ẹnu atẹ lu bi Ayọ Adebanjọ ṣe n ṣe atilẹyin fun Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour. Onanuga kọ ọ si oju opo Facebook rẹ pe lootọ Adebanjọ lẹtọ si fifi atilẹyin rẹ han fun oludije yoowu to ba wu u ṣugbọn iṣẹ ara rẹ lo n jẹ, ko yẹ ko wa maa lọ ifẹ ara rẹ mọ ẹgbẹ Afẹnifẹre lẹsẹ pe oun ti oun n fẹ naa ni ẹgbẹ ọhun pẹlu nfẹ. Adebanjọ to fesi si eyi ṣalaye iwa aisi irẹjẹ ni Afẹnifẹre n fẹ to fi gbe ijoko joko si ẹyin Peter Obi gẹgẹ bi oludije to fẹ ti lẹyin. O fi kun pe ilana iṣejọba apapọ tootọ ti oyinbo n pe ni Federalism ni Afẹnifẹre n fẹ. Ayọ Adebanjọ ni lootọ ọpọ awọn aṣiwaju ilẹ Yoruba lo ti kọminu lori igbesẹ naa sugbọn ti oun ti la ọrọ naa ye ti oun si ti jẹ ki wọn mọ pe ilana ẹni kan kii jẹ ki ilẹ fẹ ti Action Group ti Awolowo da silẹ laye ọjọun duro le lori lawọn ṣi n tẹlẹ. | Ibi tí Yorùbá ńfẹ́ kọ́ ni Adebanjo kọjú sí, ẹ̀yìn Tinubu ni Afenifere tò sí -Wale Oshun Aṣiwaju ẹgbẹ ọmọbibi ilẹ Yoruba, Afenifere Renewal Group, Ọgbẹni Olawalu Oshun, ti sọ pe Bọla Tinubu lawọn n ṣe atilẹyin fun, kii ṣe Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party. Ṣaaju ni olori Afenifere, Oloye Ayo Adebanjo sọ nibi eto kan lọjọ Aje pe Obi ni ẹgbẹ naa n tilẹyin. Ọgbẹni Oshun sọ fun BBC pe ohun ti Ẹgbẹ Afẹnifẹre Renewal Group duro ti ni ifẹ ọmọ Yoruba nile ati lẹyin odi, ti o si da awon loju pe ohun to ọgọrọ ọmọ Yoruba n fẹ naa ni ki ọmọ Yoruba to kun oju oṣuwọn o wọle sipo aarẹ. O ni kii ṣe pe ẹgbẹ naa ko ni igbagbọ ninu iṣọkan Naijiria, ati wi pe boya awọn eeyan lati ẹya miran ko ni jade. “Ohun to fa ipinnu wa lati duro ti ọmọ Yoruba laarin awọn to n dije bayii ko ju wi pe, oun lo kun oju oṣuwọn julọ ninu gbogbo oludije fun ipo aarẹ. Ọgbẹni Oshun ni Bola Tinubu, ni awọn rii pe yoo lee yanju awọn ipenija ti o n doju kọ ọmọ Naijiria, leyi ti awọn si ti n fọnrere rẹ ṣaaju akoko yii. Ọrọ ti Afẹnifere sọ yii n fidi ohun ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ipolongo ibo Bola Tinubu, Bayọ Ọnanuga sọ pe ọrọ ara oloye Adebanjọ lo n sọkii ṣe ohun ti ẹgbẹ Afẹnifẹre n fe. Asiwaju ẹgbẹ Yoruba kan ti a mọ si Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjọ ti ṣalaye idi ti ẹgbẹ naa ko fi fẹ ti oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu tabi ti PDP Atiku Abubakar lẹyin fun ibo aarẹ Naijiria ti yoo waye lọdun 2023. Asiwaju ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjọ ṣalaye nibi apero kan to ṣe pẹl’awọn akọroyin pe iṣọkan ati ilana aparo kan ko ga ju ọkan lọ pẹlu idajọ ododo lti ẹgbẹ naa duro fun lo mu ko pinnu eyi. Adebanjọ n fi apero naa fesi si ọrọ ti ileeṣẹ ipolongo idibo aarẹ fun Bola Ahmed Tinubu fi sita laipẹ yii ni ninu eyi to ti sọ ọ di mimọ pe iṣẹ ara oloye Adebanjọ lo n jẹ o ko jẹ iṣẹ ọmọ Yoruba lori Peter Obi to gbe ka ori. Oludari eto ipolongo fun ileesẹ ipolongo ibo fun Bola Tinubu, Bayọ Ọnanuga ṣalaye bu ẹnu atẹ lu bi Ayọ Adebanjọ ṣe n ṣe atilẹyin fun Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour. Onanuga kọ ọ si oju opo Facebook rẹ pe lootọ Adebanjọ lẹtọ si fifi atilẹyin rẹ han fun oludije yoowu to ba wu u ṣugbọn iṣẹ ara rẹ lo n jẹ, ko yẹ ko wa maa lọ ifẹ ara rẹ mọ ẹgbẹ Afẹnifẹre lẹsẹ pe oun ti oun n fẹ naa ni ẹgbẹ ọhun pẹlu nfẹ. Adebanjọ to fesi si eyi ṣalaye iwa aisi irẹjẹ ni Afẹnifẹre n fẹ to fi gbe ijoko joko si ẹyin Peter Obi gẹgẹ bi oludije to fẹ ti lẹyin. O fi kun pe ilana iṣejọba apapọ tootọ ti oyinbo n pe ni Federalism ni Afẹnifẹre n fẹ. Ayọ Adebanjọ ni lootọ ọpọ awọn aṣiwaju ilẹ Yoruba lo ti kọminu lori igbesẹ naa sugbọn ti oun ti la ọrọ naa ye ti oun si ti jẹ ki wọn mọ pe ilana ẹni kan kii jẹ ki ilẹ fẹ ti Action Group ti Awolowo da silẹ laye ọjọun duro le lori lawọn ṣi n tẹlẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/c031515nkk9o |
2health
| Rotten Tomatoes: Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí | Onimọ nipa fifi ounjẹ wo aisan, Olusola Malomo ti ṣalaye idi ti ko fi yẹ ki awọn eeyan to ba fẹ ra Tòmátò ni ọja maa ra ẹsa Tomato to ba ti fi ara kan isalẹ apẹrẹ. O jẹ ko di mimọ pe ko dara fun ilera eeyan rara labẹ gbogbo akoso bo ti wu ko ri. Ipo ti ipese ounjẹ fi n ja walẹ lati bii ọdun melo kan sẹyin to fi mọ jija walẹ iyi owo ati bi ìṣẹ́ ṣe n pọ sii ti mu ki ọpọlọpọ ọmọ Naijiria maa ra awọn ounjẹ to ti n bajẹ pẹlu ero ati jẹ ẹ bẹẹ bẹẹ. 'Kò sí ǹkan tó jọ tòmátò tó ní májèlé ní Nàìjíríà' Okòòwò márùn ún tí o lè bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ̀ Wo àwọn oúnjẹ márùn ún tó ń mú kí àtọ̀ ọkùnrin dára síi Iroyin bojuwo bi awọn onibara kan ṣe pinu lati bẹrẹ si maa ra Tomato to ti n bajẹ tabi fọ lara gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ọ tori pe o dinwo ju oju eyi to ṣi n dan lara lọ ati pe yoo pọ diẹ ju u lọ. Lara awọn to n ra a ti pupọ ninu wọn jẹ awọn to n se ounjẹ ta ṣalaye pe bi eeyan ba ti fọ ọ daadaa ti eeyan si bọ ọ lori ina, ṣe ni yoo da wa ni ilera pada to si dara fun jijẹ. Ẹwẹ, onimọ nipa ounjẹ jijẹ fun ilera, Olusola Malomo sọ fun BBC Yoruba ohun to ṣe pataki fun ilera eeyan nipa ẹsa ti awọn mii yan lati maa ra yii. Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ondo sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ tó dá Sotitobire láre pé kò jí ọmọ kankan gbé Akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún ló wọlé lu ọmọ mí tó fi kú, kìí ṣe bọ́ọ̀lù ló gbá - Baba akẹ́kòó Dowen fèsì Ṣé lóòtọ́ ní pé ìlúmọ̀ọ́ká agbábọ́ọ̀lù ayé àtijọ́ Teslim Thunder Balogun gbá ṣọ́ọ̀tì gbígbóná fi pa "Goal keeper"? Ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ | Rotten Tomatoes: Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí Onimọ nipa fifi ounjẹ wo aisan, Olusola Malomo ti ṣalaye idi ti ko fi yẹ ki awọn eeyan to ba fẹ ra Tòmátò ni ọja maa ra ẹsa Tomato to ba ti fi ara kan isalẹ apẹrẹ. O jẹ ko di mimọ pe ko dara fun ilera eeyan rara labẹ gbogbo akoso bo ti wu ko ri. Ipo ti ipese ounjẹ fi n ja walẹ lati bii ọdun melo kan sẹyin to fi mọ jija walẹ iyi owo ati bi ìṣẹ́ ṣe n pọ sii ti mu ki ọpọlọpọ ọmọ Naijiria maa ra awọn ounjẹ to ti n bajẹ pẹlu ero ati jẹ ẹ bẹẹ bẹẹ. 'Kò sí ǹkan tó jọ tòmátò tó ní májèlé ní Nàìjíríà' Okòòwò márùn ún tí o lè bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ̀ Wo àwọn oúnjẹ márùn ún tó ń mú kí àtọ̀ ọkùnrin dára síi Iroyin bojuwo bi awọn onibara kan ṣe pinu lati bẹrẹ si maa ra Tomato to ti n bajẹ tabi fọ lara gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ọ tori pe o dinwo ju oju eyi to ṣi n dan lara lọ ati pe yoo pọ diẹ ju u lọ. Lara awọn to n ra a ti pupọ ninu wọn jẹ awọn to n se ounjẹ ta ṣalaye pe bi eeyan ba ti fọ ọ daadaa ti eeyan si bọ ọ lori ina, ṣe ni yoo da wa ni ilera pada to si dara fun jijẹ. Ẹwẹ, onimọ nipa ounjẹ jijẹ fun ilera, Olusola Malomo sọ fun BBC Yoruba ohun to ṣe pataki fun ilera eeyan nipa ẹsa ti awọn mii yan lati maa ra yii. Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ondo sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ tó dá Sotitobire láre pé kò jí ọmọ kankan gbé Akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún ló wọlé lu ọmọ mí tó fi kú, kìí ṣe bọ́ọ̀lù ló gbá - Baba akẹ́kòó Dowen fèsì Ṣé lóòtọ́ ní pé ìlúmọ̀ọ́ká agbábọ́ọ̀lù ayé àtijọ́ Teslim Thunder Balogun gbá ṣọ́ọ̀tì gbígbóná fi pa "Goal keeper"? Ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ | https://www.bbc.com/yoruba/59530664 |
2health
| Nigeria Resident Doctor's Strike: Àwọn dókítà tí fagilé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ, sùgbọ́n... | Àwọn ẹgbẹ́ dókítà tí fagilé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ ti wọ́n gùnlẹ, sùgbgọ́n wọ́n ṣe ìlérí pé, ọjọ́rú ni àwọn yóò tó wọṣẹ́. Tí ẹ ò bá gbàgbé, àwọn dókítà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nínú oṣù kẹjọ lẹ́yìn èdè-àìyede tó bẹ́sílẹ̀ láàrín àwọn àti ìjọba àpapọ̀ lórí àwọn irinṣẹ́ àti ohunèlò tí kò tó láwọn ilé ìwòsàn ìjọba. Nínú àtẹ̀jáde ti wọ́n fi sita lórí àfẹnukò wọn tí akọ̀wé ẹgbẹ́ náà Expe Philips Uche fọwọ́sí lẹ́yìn ìpàdé tí àwọn aṣojú NMA àti NARD ṣe nílùú Abuja ni bi ti ẹgbẹ́ àwọn Dókíta (NMA) tí wọ́n sì gbà wọ́n ni ìmọ̀ràn láti fòpin sí ìyànsẹ́lódì. Nínú ìpàdé náà ẹgbẹ́ NMA paá ni dandan pé kí ìgbìmọ̀ tó n mójú tó mímójú tó àdéhùn ìjọba tí wọ́n fi ọwọ́ sí ni ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹjọ ọdún yìí ri dájú pé ìjọba mú àdéhùn wọn ṣẹ. Bákan náà lo ni ki ìgbìmọ̀ ọ̀hún jábọ̀ padà fún àwọn alága NMA ìpińlẹ̀ kọ̀ọ̀kan tó fi mọ́ alága ti ilúi Abuja lóòrèkóòrè lórí ilọsíwájú tó bá wáyé. Gẹ́gẹ́ bi alága NARD Godiya Ishaya ṣe sọ, ẹgbẹ́ tí fagilé òyànṣẹ́lódì. Ó ní : " A ti fagilé ìyànṣẹ́lódì, à ọ sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní aago mẹ́jọ owúrọ̀ Ọjọ́rú. A p ẹnupọ̀ láti fagilé ìyànṣẹ́lódì yìí ní ìdájí owúrọ̀ òní." "A pe ìpàdé pàjáwìrì ni ago márùn àbọ̀ ọj Aikú títí dí òwúrọ̀ òní, à jọ́ ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àṣeyọrí wa, a si wòó pé kí a fopin sí ìyànṣẹ́lódì tó n lọ." Ọ̀sẹ̀ mẹ́sàn gbáko ni ìyànṣẹ́lódì náà pé ní òní ọjọ́ Ajé, èyí tí ó sì tí ṣe àkọ́bá fún àwọn ilé ìwòsàn ìjọba jákèjádò Nàìjíríà, tí ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn sì ti fara gbá nínú rẹ. | Nigeria Resident Doctor's Strike: Àwọn dókítà tí fagilé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ, sùgbọ́n... Àwọn ẹgbẹ́ dókítà tí fagilé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ ti wọ́n gùnlẹ, sùgbgọ́n wọ́n ṣe ìlérí pé, ọjọ́rú ni àwọn yóò tó wọṣẹ́. Tí ẹ ò bá gbàgbé, àwọn dókítà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nínú oṣù kẹjọ lẹ́yìn èdè-àìyede tó bẹ́sílẹ̀ láàrín àwọn àti ìjọba àpapọ̀ lórí àwọn irinṣẹ́ àti ohunèlò tí kò tó láwọn ilé ìwòsàn ìjọba. Nínú àtẹ̀jáde ti wọ́n fi sita lórí àfẹnukò wọn tí akọ̀wé ẹgbẹ́ náà Expe Philips Uche fọwọ́sí lẹ́yìn ìpàdé tí àwọn aṣojú NMA àti NARD ṣe nílùú Abuja ni bi ti ẹgbẹ́ àwọn Dókíta (NMA) tí wọ́n sì gbà wọ́n ni ìmọ̀ràn láti fòpin sí ìyànsẹ́lódì. Nínú ìpàdé náà ẹgbẹ́ NMA paá ni dandan pé kí ìgbìmọ̀ tó n mójú tó mímójú tó àdéhùn ìjọba tí wọ́n fi ọwọ́ sí ni ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹjọ ọdún yìí ri dájú pé ìjọba mú àdéhùn wọn ṣẹ. Bákan náà lo ni ki ìgbìmọ̀ ọ̀hún jábọ̀ padà fún àwọn alága NMA ìpińlẹ̀ kọ̀ọ̀kan tó fi mọ́ alága ti ilúi Abuja lóòrèkóòrè lórí ilọsíwájú tó bá wáyé. Gẹ́gẹ́ bi alága NARD Godiya Ishaya ṣe sọ, ẹgbẹ́ tí fagilé òyànṣẹ́lódì. Ó ní : " A ti fagilé ìyànṣẹ́lódì, à ọ sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní aago mẹ́jọ owúrọ̀ Ọjọ́rú. A p ẹnupọ̀ láti fagilé ìyànṣẹ́lódì yìí ní ìdájí owúrọ̀ òní." "A pe ìpàdé pàjáwìrì ni ago márùn àbọ̀ ọj Aikú títí dí òwúrọ̀ òní, à jọ́ ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àṣeyọrí wa, a si wòó pé kí a fopin sí ìyànṣẹ́lódì tó n lọ." Ọ̀sẹ̀ mẹ́sàn gbáko ni ìyànṣẹ́lódì náà pé ní òní ọjọ́ Ajé, èyí tí ó sì tí ṣe àkọ́bá fún àwọn ilé ìwòsàn ìjọba jákèjádò Nàìjíríà, tí ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn sì ti fara gbá nínú rẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/media-58783782 |
4religion
| Shiloh 2020: Oyedepo ní òun kò le tòṣì láéláé! Ẹni tó bá ń bínú kàn ń bínú lásán ni | Oludasilẹ ijọ Living Faith ti ọpọ mọ si Winners, Biṣọọbu David Oyedepo tun ti sọ pe oun ko le toṣi laelae! Biṣọọbu Oyedepo sọrọ yii nigba ti o n waasu nibi akanṣe eto ọlọdọọdun ijọ Winners, Shiloh 2020 niluu Ota, ipinlẹ Ogun. Biṣọọbu Oyedepo ni majẹmu ti Ọlọrun ti la kalẹ ninu iwe mimọ ti oun n tẹle ko le jẹ ki oṣi mọ ile oun laelae. O ṣalaye pe niwọn igba ti orun ba n yọ loke ti ilẹ si n su u, majẹmu to sọ oun di ọlọrọ ko le yipada laelae. Biṣọọbu Oyedepo ni Ọlọrun sọ fun oun pe ilọrọ ninu Oluwa kii ṣe ileri, kii sii ṣe ọrọ adura ati aawẹ. Ti eeyan ko ba ko ipa tirẹ, Ọlọrun naa ko ni ṣe ohun kan.'' ''Nigba naa ni mo ke Yeeeehhh! Mo o le toṣi laelae. Ẹni to ba fẹ lọrọ ninu Oluwa ko gbọdọ fi idamẹwa ati ififunni ṣere,'' Oyedepo lo sọ bẹẹ. Ọlọrun tun sọ ohun miiran fun mi lẹyin ti mo ka iwe ti Kenneth ati Gloria Copeland lori ilọrọ ninu Oluwa tan. Oyedepo ni: ''O sọ fun mi pe bi Oun ṣe maa n ṣi ferese ọrun si awọn eeyan naa ni Oun maa ṣi ferese ọrun sori ileeṣẹ. Apẹẹrẹ iru rẹ to wa ninu Bibeli ni Abarahamu to san idamẹwaa lori gbogbo ohun to ko bọ lati oju ogun. Biṣọọbu Oyedepo ni lati igba naa ni ijọ Winners ti bẹrẹ si ni san idamẹwaa eyi ti o si n jẹ ki ferese ọrun maa tubọ ṣi sori ijọ naa sii. Ìjọ 10,000 tuntun ni a dá sílẹ̀ láì gba owó ọrẹ lọ́wọ́ ọmọ ìjọ lásìkò àrùn Coronavirus- Oyedepo Oluṣọ agutan agba ijọ Living Faith, pasitọ David Oyedepo ti ṣi aṣọ loju eegun pe bo tilẹ jẹ arun Covid-19 ba gbogbo agbaye finra lọdun 2020, ẹka ẹgbẹrun mẹwaa tuntun ni ijọ naa ṣi lai gba kọbọ lọwọ ọmọ ijọ kankan. Oyedepo lo sọ ọrọ naa lọjọ Abamẹta to jẹ aṣekagba ipade adura Shiloh, eyii to maa n waye lọdọdun. Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "bo tilẹ jẹ pe arun naa n dun mọhuru mọhuru, ẹgbẹrun mẹwaa ẹka tuntun ni ijọ yii ṣi lai gba owo ọrẹ kankan, a o fi oju imu eṣu danrin." Nigba to n sọrọ ṣaaju nipa arun Covid-19, Oyedepe sọ pe oun ko gbagbọ pe Covid-19 kan wa nibi kankan . O ni "ti wọn ba bere lọwọ mi nipa Covid-19, esi mi ko ju pe, Covid-19 wa, bẹẹ ni ko si." "Ẹni to ba gbagbọ ninu Covid-19 ni arun naa yoo ran, ẹni ti ko ba gbagbọ ninu rẹ ko ni lugbadi arun naa." Lẹyin naa lo sọ siwaju si pe ọpọ eeyan lo ti ri iwosan gba lọwọ arun Covid-19 ninu ijọ oun. | Shiloh 2020: Oyedepo ní òun kò le tòṣì láéláé! Ẹni tó bá ń bínú kàn ń bínú lásán ni Oludasilẹ ijọ Living Faith ti ọpọ mọ si Winners, Biṣọọbu David Oyedepo tun ti sọ pe oun ko le toṣi laelae! Biṣọọbu Oyedepo sọrọ yii nigba ti o n waasu nibi akanṣe eto ọlọdọọdun ijọ Winners, Shiloh 2020 niluu Ota, ipinlẹ Ogun. Biṣọọbu Oyedepo ni majẹmu ti Ọlọrun ti la kalẹ ninu iwe mimọ ti oun n tẹle ko le jẹ ki oṣi mọ ile oun laelae. O ṣalaye pe niwọn igba ti orun ba n yọ loke ti ilẹ si n su u, majẹmu to sọ oun di ọlọrọ ko le yipada laelae. Biṣọọbu Oyedepo ni Ọlọrun sọ fun oun pe ilọrọ ninu Oluwa kii ṣe ileri, kii sii ṣe ọrọ adura ati aawẹ. Ti eeyan ko ba ko ipa tirẹ, Ọlọrun naa ko ni ṣe ohun kan.'' ''Nigba naa ni mo ke Yeeeehhh! Mo o le toṣi laelae. Ẹni to ba fẹ lọrọ ninu Oluwa ko gbọdọ fi idamẹwa ati ififunni ṣere,'' Oyedepo lo sọ bẹẹ. Ọlọrun tun sọ ohun miiran fun mi lẹyin ti mo ka iwe ti Kenneth ati Gloria Copeland lori ilọrọ ninu Oluwa tan. Oyedepo ni: ''O sọ fun mi pe bi Oun ṣe maa n ṣi ferese ọrun si awọn eeyan naa ni Oun maa ṣi ferese ọrun sori ileeṣẹ. Apẹẹrẹ iru rẹ to wa ninu Bibeli ni Abarahamu to san idamẹwaa lori gbogbo ohun to ko bọ lati oju ogun. Biṣọọbu Oyedepo ni lati igba naa ni ijọ Winners ti bẹrẹ si ni san idamẹwaa eyi ti o si n jẹ ki ferese ọrun maa tubọ ṣi sori ijọ naa sii. Ìjọ 10,000 tuntun ni a dá sílẹ̀ láì gba owó ọrẹ lọ́wọ́ ọmọ ìjọ lásìkò àrùn Coronavirus- Oyedepo Oluṣọ agutan agba ijọ Living Faith, pasitọ David Oyedepo ti ṣi aṣọ loju eegun pe bo tilẹ jẹ arun Covid-19 ba gbogbo agbaye finra lọdun 2020, ẹka ẹgbẹrun mẹwaa tuntun ni ijọ naa ṣi lai gba kọbọ lọwọ ọmọ ijọ kankan. Oyedepo lo sọ ọrọ naa lọjọ Abamẹta to jẹ aṣekagba ipade adura Shiloh, eyii to maa n waye lọdọdun. Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "bo tilẹ jẹ pe arun naa n dun mọhuru mọhuru, ẹgbẹrun mẹwaa ẹka tuntun ni ijọ yii ṣi lai gba owo ọrẹ kankan, a o fi oju imu eṣu danrin." Nigba to n sọrọ ṣaaju nipa arun Covid-19, Oyedepe sọ pe oun ko gbagbọ pe Covid-19 kan wa nibi kankan . O ni "ti wọn ba bere lọwọ mi nipa Covid-19, esi mi ko ju pe, Covid-19 wa, bẹẹ ni ko si." "Ẹni to ba gbagbọ ninu Covid-19 ni arun naa yoo ran, ẹni ti ko ba gbagbọ ninu rẹ ko ni lugbadi arun naa." Lẹyin naa lo sọ siwaju si pe ọpọ eeyan lo ti ri iwosan gba lọwọ arun Covid-19 ninu ijọ oun. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-55289586 |
1entertainment
| Davido: Àpètàn orukọ̀ ọmọ tuntun náà ní David Adedeji Ifeanyi Adeleke | Ayọ abara tintin. David Adeleke, ti gbogbo eeyan mọ si Davido ti kede pe, Oluwa ti fi ọmọkunrin kan lanti-lanti da oun ati aya oun, Chioma, lọla. Owurọ ọjọ Aiku ni Davido kede bẹẹ loju opo Instagram rẹ, to si ni Ọmọọba ti de, ile iwosan kan nilu London si ni Chioma bimọ naa si. O wa pe orukọ ọmọ ọhun ni David Adedeji Ifeanyi Adeleke Jnr pẹlu afikun pe inu oun dun pupọ si iroyin ayọ naa. Davido ni "Mo nifẹ aya mi pupọ, koda obinrin alagbara ni", to si jẹ pe nigba ti awọn olorin to jẹ akẹẹgbẹ Davido n lọ sibi ami ẹyẹ fawọn olorin, Headies Award, yara igbẹbi ni Davido wa, to n rawọ rasẹ si Ọlọrun pe, ko sọ aya oun kalẹ layọ. Chioma, afẹsọna Davido lo ti kọkọ kede loju opo Twitter rẹ nirọlẹ ana pe oun wa nile igbẹbi, ti ọpọ eeyan si ti n se adura fun pe yoo bi wẹrẹ. Koda, oun naa tun ti kede loju opo Instagram rẹ pe Oluwa ti sọ oun layọ. Wayi o, awọn ọmọ Naijiria ti n se jaginni yodo pẹlu ọba orin naa fun ayọ ọmọkunrin jojolo to baa lalejo naa, bi o tilẹ jẹ pe obinrin meji ọtọọtọ ti bi ọmọbinrin meji fun tẹlẹ. | Davido: Àpètàn orukọ̀ ọmọ tuntun náà ní David Adedeji Ifeanyi Adeleke Ayọ abara tintin. David Adeleke, ti gbogbo eeyan mọ si Davido ti kede pe, Oluwa ti fi ọmọkunrin kan lanti-lanti da oun ati aya oun, Chioma, lọla. Owurọ ọjọ Aiku ni Davido kede bẹẹ loju opo Instagram rẹ, to si ni Ọmọọba ti de, ile iwosan kan nilu London si ni Chioma bimọ naa si. O wa pe orukọ ọmọ ọhun ni David Adedeji Ifeanyi Adeleke Jnr pẹlu afikun pe inu oun dun pupọ si iroyin ayọ naa. Davido ni "Mo nifẹ aya mi pupọ, koda obinrin alagbara ni", to si jẹ pe nigba ti awọn olorin to jẹ akẹẹgbẹ Davido n lọ sibi ami ẹyẹ fawọn olorin, Headies Award, yara igbẹbi ni Davido wa, to n rawọ rasẹ si Ọlọrun pe, ko sọ aya oun kalẹ layọ. Chioma, afẹsọna Davido lo ti kọkọ kede loju opo Twitter rẹ nirọlẹ ana pe oun wa nile igbẹbi, ti ọpọ eeyan si ti n se adura fun pe yoo bi wẹrẹ. Koda, oun naa tun ti kede loju opo Instagram rẹ pe Oluwa ti sọ oun layọ. Wayi o, awọn ọmọ Naijiria ti n se jaginni yodo pẹlu ọba orin naa fun ayọ ọmọkunrin jojolo to baa lalejo naa, bi o tilẹ jẹ pe obinrin meji ọtọọtọ ti bi ọmọbinrin meji fun tẹlẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-50114244 |
5sports
| Egúngún Arsenal tó kọ́kọ́ jó, ìran góòlù méjì ló padà wò lọ́wọ́ Chelsea | Ọrọ naa ṣe awọn ololufẹ ẹgbẹ Arsenal bi ere ṣugbọn nigba ti adari ere yoo fọn fere, wọn ti fidirẹmi lọwọ Chelsea. Goolu meji si ookan ni ikọ Frank Lampard fi tẹyin gberu Arsenal ni agboole wọn tii ṣe Emirates. Pẹlu esi yi, Chelsea ti ni ami marundinlogoji ti wọn si wa ni ipo Kẹrin lori afara liigi Premiership.Arsenal wa ni ipo kejila Pierre Emerick Aubameyang lo kọkọ jẹ goolu fun Arsenal ni abala kini ipade naa. Ninu ẹgbẹ mejeeji,Arsenal lo pitu gidi gaan ni abala kini ti awọn ọmọ Frank Lampard ko si rojutu ara wọn . Ninu abala keji ni nnkan ti yi pada ti Chelsea si fi ina goolu meji jo Arsenal lara mọle. Aṣiṣe lati ọwọ aṣọle Arsenal lo ṣokunfa goolu akọkọ ti Chelsea jẹ lati ọwọ Jorginho. Tammy Abraham tojẹ atamatase Chelsea ti o ni goolu julọ ni saa bọọlu yi lo pari ijo pẹlu goolu ẹlẹkeeji ni iṣeju mẹ́tàdínláàdọ́rùn ún. Bayi,ami mọkanla ni Chelsea yoo fi ṣagba Arsenal wọ ọdun 2020 lori afara liigi Premiership. | Egúngún Arsenal tó kọ́kọ́ jó, ìran góòlù méjì ló padà wò lọ́wọ́ Chelsea Ọrọ naa ṣe awọn ololufẹ ẹgbẹ Arsenal bi ere ṣugbọn nigba ti adari ere yoo fọn fere, wọn ti fidirẹmi lọwọ Chelsea. Goolu meji si ookan ni ikọ Frank Lampard fi tẹyin gberu Arsenal ni agboole wọn tii ṣe Emirates. Pẹlu esi yi, Chelsea ti ni ami marundinlogoji ti wọn si wa ni ipo Kẹrin lori afara liigi Premiership.Arsenal wa ni ipo kejila Pierre Emerick Aubameyang lo kọkọ jẹ goolu fun Arsenal ni abala kini ipade naa. Ninu ẹgbẹ mejeeji,Arsenal lo pitu gidi gaan ni abala kini ti awọn ọmọ Frank Lampard ko si rojutu ara wọn . Ninu abala keji ni nnkan ti yi pada ti Chelsea si fi ina goolu meji jo Arsenal lara mọle. Aṣiṣe lati ọwọ aṣọle Arsenal lo ṣokunfa goolu akọkọ ti Chelsea jẹ lati ọwọ Jorginho. Tammy Abraham tojẹ atamatase Chelsea ti o ni goolu julọ ni saa bọọlu yi lo pari ijo pẹlu goolu ẹlẹkeeji ni iṣeju mẹ́tàdínláàdọ́rùn ún. Bayi,ami mọkanla ni Chelsea yoo fi ṣagba Arsenal wọ ọdun 2020 lori afara liigi Premiership. | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-50941414 |
1entertainment
| Nollywood: Saheed Balogun àti Shina Peters lọ sí ilé Ààrẹ Buhari lÀbuja, wọ́n gba àmì ẹ̀yẹ | Ki ni agba oṣere, Saheed Balogun ati agba akọrin Sir Shina Peters lọ ṣe ni ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria nilu Abuja, nibi ti aworan wọn ati awọn atawọn eekan elere tiata miran ti jẹyọ pẹlu amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori ọrọ iroyin ati ipolongo, Ọgbẹni Fẹmi Adesina. Agba oṣere ati akọrin meji naa wa lara ikọ ẹgbẹ kan ti wọn pe ni ' Ambassadors of Voice for Change' to ṣe abẹwo si Ọgbẹni Fẹmi Adesina nibi ti wọn ti fi ami ẹyẹ da a lọla nilu Abuja. Awọn agba osere bii Mr. Ibu, Onyekweli Harry B, Gentle Jack, Ben Kure atawọn eekan miran latiẹya gbogbo lorilẹede Naijiria wa lara awọn ti wọn wa ninu ẹgbẹ naa wa nibi abẹwo naa ti Ahmed Bala ko sodi lọ. Amugbalẹgbẹ fun Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin ati ipolongo naa wa kan sara sawọn agba amuludun ọhun fun ipa ti wọn n ko lati rii pe iṣọkan ati alaafia di igi alọye lorilẹede Naijiria. Ọgbẹni Adeṣina fi kun un pe awọn olulaja atawọn to n lepa alaafia lorilẹede Naijiria nilo bayii, kii ṣe awọn ọbayejẹ ti yoo pagidina idagbasoko ati iṣọkan Naijiria. Bakan naa lo tun ṣalaye pe ijọba Buhari yoo tubọ maa ṣe atilẹyin to ba yẹ fun awọn ọmọ Naijiria to n ṣiṣẹ takuntakun lati mu alaafia gbooro sii. | Nollywood: Saheed Balogun àti Shina Peters lọ sí ilé Ààrẹ Buhari lÀbuja, wọ́n gba àmì ẹ̀yẹ Ki ni agba oṣere, Saheed Balogun ati agba akọrin Sir Shina Peters lọ ṣe ni ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria nilu Abuja, nibi ti aworan wọn ati awọn atawọn eekan elere tiata miran ti jẹyọ pẹlu amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori ọrọ iroyin ati ipolongo, Ọgbẹni Fẹmi Adesina. Agba oṣere ati akọrin meji naa wa lara ikọ ẹgbẹ kan ti wọn pe ni ' Ambassadors of Voice for Change' to ṣe abẹwo si Ọgbẹni Fẹmi Adesina nibi ti wọn ti fi ami ẹyẹ da a lọla nilu Abuja. Awọn agba osere bii Mr. Ibu, Onyekweli Harry B, Gentle Jack, Ben Kure atawọn eekan miran latiẹya gbogbo lorilẹede Naijiria wa lara awọn ti wọn wa ninu ẹgbẹ naa wa nibi abẹwo naa ti Ahmed Bala ko sodi lọ. Amugbalẹgbẹ fun Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin ati ipolongo naa wa kan sara sawọn agba amuludun ọhun fun ipa ti wọn n ko lati rii pe iṣọkan ati alaafia di igi alọye lorilẹede Naijiria. Ọgbẹni Adeṣina fi kun un pe awọn olulaja atawọn to n lepa alaafia lorilẹede Naijiria nilo bayii, kii ṣe awọn ọbayejẹ ti yoo pagidina idagbasoko ati iṣọkan Naijiria. Bakan naa lo tun ṣalaye pe ijọba Buhari yoo tubọ maa ṣe atilẹyin to ba yẹ fun awọn ọmọ Naijiria to n ṣiṣẹ takuntakun lati mu alaafia gbooro sii. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60006854 |
5sports
| Anthony Joshua: Ajagba akẹ̀ṣẹ́ ọmọ Nàìjíríà lóun ṣetán láti f'ẹ̀ṣẹ́ dín dòdò ìyà fún AJ | Yoruba bọ, wọn ni o di oni karangida, adiẹ n jẹ ifun ara wọn. Bayii lọrọ ri abẹṣẹ ku bi ojo ọmọ Naijiria, Efe Ajagba to ni oun ṣetan lati fi ẹṣẹ din dodo iya fun ogbontarigi akẹṣẹ Anthony Joshua. Ilẹ Amẹrika ni Ajagba to ti ṣoju orilẹede Naijiria ri ninu idije ''Olympics'' fi ṣe ibugbe bayii lẹyin to ti wa niluu Eko fun ọpọlọpọ ọdun. Ọrọ naa da bi ẹni to maa ku pade ẹni to maa pa, nirori Joshua gan an funra rẹ ti sọ tẹlẹ pe o wu oun lati fija pẹta pẹlu akẹṣẹ to jẹ ọmọbibi ilẹ Afirika bi t'oun naa. Ajagba tiẹ ti bẹrẹ si ni sọ ọna ti o fi le fẹyin AJ gbalẹ ti wọn ba koju ara wọn. Ajagba sọ fawọn akọroyin pe ko ba wu oun ki Joshua gba lati ba oun ja lorilẹede Naijiria tawọn mejeeji ti wa. Abẹsẹ ku bi ojo ọmọ Naijiria ṣalaye pe lootọọ ni pe Joshua lagbara, amọ ọgban inu loun maa fi ṣẹ AJ leegun ẹyin tawọn koju ara awọn. O ni ati oun ati Joshua lawọn jọ lagbara ṣugbọn o ni ọgbọn ju ọgbọn lọ. Ajagba ni otitọ ni pe Joshua ti gba ami ẹyẹ goolu ninu idije ''Olympics'' ri, oun si tun ni abẹṣẹ ku bi ojo to lami lahaka taye ti aye n fẹ lọwọ bayii. Oun oun naa gboṣuba fun AJ fun awọn aṣeyọri rẹ lagbo ẹṣẹ kikan, amọ oun mọ awọn ibi ti Joshua ku si ninu ẹṣẹ kikan. Joshua gba awọn igbanu rẹ mẹtẹẹta, IBF, WBA ati WBO pada lọwọ Andy Ruiz Jr pada lẹyin ti Ruiz ti kọkọ lu u bi aṣọ ofi nigba ti wọn kọkọ koju ara wọn. Joshua naa fẹ ṣe bi agbọjẹ ninu ẹṣẹ kikan, oloogbe Muhammad Ali to ba George Foreman ja ni Zaire lọdun 1974. Amọ Ajagba ti kepe Joshua pe ko jẹ ki awọn ṣe ere ọwọ papọ ni Naijiria, o ni ti o ba ti ya eegun Joshua, o ti ya ọlọrẹ t'oun naa. | Anthony Joshua: Ajagba akẹ̀ṣẹ́ ọmọ Nàìjíríà lóun ṣetán láti f'ẹ̀ṣẹ́ dín dòdò ìyà fún AJ Yoruba bọ, wọn ni o di oni karangida, adiẹ n jẹ ifun ara wọn. Bayii lọrọ ri abẹṣẹ ku bi ojo ọmọ Naijiria, Efe Ajagba to ni oun ṣetan lati fi ẹṣẹ din dodo iya fun ogbontarigi akẹṣẹ Anthony Joshua. Ilẹ Amẹrika ni Ajagba to ti ṣoju orilẹede Naijiria ri ninu idije ''Olympics'' fi ṣe ibugbe bayii lẹyin to ti wa niluu Eko fun ọpọlọpọ ọdun. Ọrọ naa da bi ẹni to maa ku pade ẹni to maa pa, nirori Joshua gan an funra rẹ ti sọ tẹlẹ pe o wu oun lati fija pẹta pẹlu akẹṣẹ to jẹ ọmọbibi ilẹ Afirika bi t'oun naa. Ajagba tiẹ ti bẹrẹ si ni sọ ọna ti o fi le fẹyin AJ gbalẹ ti wọn ba koju ara wọn. Ajagba sọ fawọn akọroyin pe ko ba wu oun ki Joshua gba lati ba oun ja lorilẹede Naijiria tawọn mejeeji ti wa. Abẹsẹ ku bi ojo ọmọ Naijiria ṣalaye pe lootọọ ni pe Joshua lagbara, amọ ọgban inu loun maa fi ṣẹ AJ leegun ẹyin tawọn koju ara awọn. O ni ati oun ati Joshua lawọn jọ lagbara ṣugbọn o ni ọgbọn ju ọgbọn lọ. Ajagba ni otitọ ni pe Joshua ti gba ami ẹyẹ goolu ninu idije ''Olympics'' ri, oun si tun ni abẹṣẹ ku bi ojo to lami lahaka taye ti aye n fẹ lọwọ bayii. Oun oun naa gboṣuba fun AJ fun awọn aṣeyọri rẹ lagbo ẹṣẹ kikan, amọ oun mọ awọn ibi ti Joshua ku si ninu ẹṣẹ kikan. Joshua gba awọn igbanu rẹ mẹtẹẹta, IBF, WBA ati WBO pada lọwọ Andy Ruiz Jr pada lẹyin ti Ruiz ti kọkọ lu u bi aṣọ ofi nigba ti wọn kọkọ koju ara wọn. Joshua naa fẹ ṣe bi agbọjẹ ninu ẹṣẹ kikan, oloogbe Muhammad Ali to ba George Foreman ja ni Zaire lọdun 1974. Amọ Ajagba ti kepe Joshua pe ko jẹ ki awọn ṣe ere ọwọ papọ ni Naijiria, o ni ti o ba ti ya eegun Joshua, o ti ya ọlọrẹ t'oun naa. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-54009604 |
3politics
| 2023 Presidency: Iṣẹ́ Ọlọ́run tí mo gbé dáni kọjá ipò Ààrẹ Nàìjíríà – Bíṣọ̀ọ̀bù David Oyedepo | Bí oníwá àti ẹlẹ́yìn ṣe ti ń kéde láti fi èròńgbà àti ìpinu wọn hàn láti díje sípò Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, adarí ìjọ Living Faith Church Worldwide tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Winners Chapel, Bíṣọ̀ọ̀bù David Oyedepo ní gbígbégbá òṣèlú fún òun ní àsìkò yìí dàbí kí ènìyàn máa padà sẹ́yìn. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi àpérò kan, Oyedepo ní ó ti jù fún òun láti gbégbá tàbí máa díje du ipò Ààrẹ fún òun lásìkò yìí. Bákan náà ló rọ àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ láti ní ìfarajìn sí sínsin Ọlọ́run bó ṣe tọ́ kí Ọlọ́run le máa tó wọn ní gbogbo ìgbésí ayé wọn. Oyedepo ní òun ní ìgbàgbọ́ nínú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni òun ṣì fi wà ní orílẹ̀ èdè yìí títí di àsìkò yìí tí òun sì ń fi gbogbo ìgbà àti tinútinú òun gbàdúrà pé kí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà dára ju bó ṣe wà yìí lọ. Ó fi kun pé bí àwọn kan bá ń pe òun láti wá ṣe Ààrẹ Nàìjíríà túnmọ̀ sí wí pé òun ń padà sẹ́yìn ni nítorí òun tí Ọlọ́run pe òun fún jẹ́ láti sin gbogbo àgbáyé. Ó tẹ̀síwájú wí pé láti ọdún 1984 ni òun ti rí ìpè Ọlọ́run láti sìn-ín . "Kódà èṣù gan náà ms wí pé kò sí wí pé kò sí bí ènìyàn ṣe máa jókòó ti Ọlọ́run tó ma wá jogun òfo." "Láti ìgbà tí mo ti wà ní ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni mo ti máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé mi ò fẹ́ fi ìlú kan sílẹ̀ bí mo ṣe ba." Ó ní iṣẹ́ Ọlọ́run kò sú òun láti ọdún 1976 tí òun ti bá Ọlọ́run pàdé. | 2023 Presidency: Iṣẹ́ Ọlọ́run tí mo gbé dáni kọjá ipò Ààrẹ Nàìjíríà – Bíṣọ̀ọ̀bù David Oyedepo Bí oníwá àti ẹlẹ́yìn ṣe ti ń kéde láti fi èròńgbà àti ìpinu wọn hàn láti díje sípò Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, adarí ìjọ Living Faith Church Worldwide tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Winners Chapel, Bíṣọ̀ọ̀bù David Oyedepo ní gbígbégbá òṣèlú fún òun ní àsìkò yìí dàbí kí ènìyàn máa padà sẹ́yìn. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi àpérò kan, Oyedepo ní ó ti jù fún òun láti gbégbá tàbí máa díje du ipò Ààrẹ fún òun lásìkò yìí. Bákan náà ló rọ àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ láti ní ìfarajìn sí sínsin Ọlọ́run bó ṣe tọ́ kí Ọlọ́run le máa tó wọn ní gbogbo ìgbésí ayé wọn. Oyedepo ní òun ní ìgbàgbọ́ nínú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni òun ṣì fi wà ní orílẹ̀ èdè yìí títí di àsìkò yìí tí òun sì ń fi gbogbo ìgbà àti tinútinú òun gbàdúrà pé kí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà dára ju bó ṣe wà yìí lọ. Ó fi kun pé bí àwọn kan bá ń pe òun láti wá ṣe Ààrẹ Nàìjíríà túnmọ̀ sí wí pé òun ń padà sẹ́yìn ni nítorí òun tí Ọlọ́run pe òun fún jẹ́ láti sin gbogbo àgbáyé. Ó tẹ̀síwájú wí pé láti ọdún 1984 ni òun ti rí ìpè Ọlọ́run láti sìn-ín . "Kódà èṣù gan náà ms wí pé kò sí wí pé kò sí bí ènìyàn ṣe máa jókòó ti Ọlọ́run tó ma wá jogun òfo." "Láti ìgbà tí mo ti wà ní ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni mo ti máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé mi ò fẹ́ fi ìlú kan sílẹ̀ bí mo ṣe ba." Ó ní iṣẹ́ Ọlọ́run kò sú òun láti ọdún 1976 tí òun ti bá Ọlọ́run pàdé. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61372664 |
3politics
| Makinde vs Adelabu: Makinde ní ìjọba Ọyọ yàtọ̀ sí ti Ọṣun àbí Ekiti tí APC lé dànù | Ẹsẹ ko gba ero nile ijọba to wa nilu Ibadan loni nigba ti ọpọ ero wa se abẹwo awa lẹyin rẹ si gomina Seyi Makinde lati safihan ifẹ ti wọn ni si. Nigba to n gbalejo awọn ọgọọrọ eeyan naa, Gomina Seyi Makinde ni se ni ẹgbẹ oselu APC dabi afomọ ti ko ni gbongbo, to si n wa gbongbo ti yoo dirọ mọ pẹlu asẹ ile ẹjọ. O fikun pe ohun to n waye ni ipinlẹ Ọyọ ko lee dabi awọn isẹlẹ to ti waye sẹyin nipinlẹ Ọsun ati Ekiti nibi ti idajọ ile ẹjọ ti le ijọba to wa lori aleefa kuro. | Makinde vs Adelabu: Makinde ní ìjọba Ọyọ yàtọ̀ sí ti Ọṣun àbí Ekiti tí APC lé dànù Ẹsẹ ko gba ero nile ijọba to wa nilu Ibadan loni nigba ti ọpọ ero wa se abẹwo awa lẹyin rẹ si gomina Seyi Makinde lati safihan ifẹ ti wọn ni si. Nigba to n gbalejo awọn ọgọọrọ eeyan naa, Gomina Seyi Makinde ni se ni ẹgbẹ oselu APC dabi afomọ ti ko ni gbongbo, to si n wa gbongbo ti yoo dirọ mọ pẹlu asẹ ile ẹjọ. O fikun pe ohun to n waye ni ipinlẹ Ọyọ ko lee dabi awọn isẹlẹ to ti waye sẹyin nipinlẹ Ọsun ati Ekiti nibi ti idajọ ile ẹjọ ti le ijọba to wa lori aleefa kuro. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-50399017 |
3politics
| Nigeria population: Buhari tako ọmọ bẹẹrẹ òṣì bẹẹrẹ ní Nàìjíríà, ó ṣàgbékalẹ̀ ètò láti dẹ́kun rẹ̀ | Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe agbekalẹ eto ti yoo ṣe adinku ọmọ bẹẹrẹ oṣi bẹẹrẹ lorilẹede Naijiria. Buhari to ṣe agbekalẹ eto naa niluu Abuja sọ pe o ṣe pataki bayii lati mu ifeto sọmọ bibi lọkunkundun. Buhari tun ṣe agbekalẹ eto mii ti yoo ṣe iranwọ lori ati dẹkun bi awọn eeyan ṣe n pọ sii ni Naijiria. Buhari ṣe agbekalẹ eto ifeto sọmọ bibi Aarẹ Buhari ṣalaye pe ohun to bi eto ifeto sọmọ bibi wa ni lati mu ibayegbadun ba awọn ọmọ Naijiria. Buhari ni eyi wa lara awọn eto ijọba ẹgbẹ oṣelu APC to wa lode bayii. Eto yii yoo ṣe iranwọ lori bi adinku yoo ṣe ba bi ọpọ eeyan ṣe n bi ọmọ silẹ lọpọ yanturu. Ara awọn ọna ti ijọba fẹ gba lati ṣe eto ọhun ni nipa ilanilọyẹ lori ifeto sọmọ bibi. Aarẹ Buhari gbagbọ pe eto yii yoo ran ọpọ eeyan lọwọ lati fi alafao si aarin awọn ọmọ wọn. Buhari kọminu lori bi Naijiria ṣe pọ julọ l'Afrika Aarẹ Buhari ni orilẹede naijiria lo pọ julọ nilẹ Afirika nigba to tun jẹ orilẹede to wa ni ipo keje lagbaye. Buhari ni Naijiria wa lara awọn orilẹede diẹ lagbaaye to ni ọdọ julọ. Aarẹ ni ida mejilelaadọrin ninu ọgọrun awọn ọdọ yii ni ọjọ ori wọn ko to ọgbọn ọdun. Bakan naa ni Buhari sọ pe idaji awọn obinrin ninu awọn ọdọ yii lo wa ni asiko ti wọn ṣe abiamọ tori ọjọ ori bẹrẹ lati ọdun mẹẹdogun si ọdun mọkadinlaadọta. Ọna abayọ si ọmọ bẹẹrẹ oṣi bẹẹrẹ Buhari ni ijọba ko ni dẹkun lilo eto ẹkọ to peye lati maa la awọn eeyan lọyẹ. Aarẹ ni eto ẹkọ yoo ṣe iranwọ papaa julọ fawọn obinrin to ba jẹ ọmọde tori awọn ni wọn le gboyun nigba kugba. Buhari tun sọ pe eto ikaniyan to n bọ yoo tun ṣe iranwọ lati mọ ọna lati mu adinku ba ọmọ bẹẹrẹ oṣi bẹẹrẹ. Ni bayii, akọsilẹ fihan pe eeyan to wa ni Naijiria le ni ẹgbẹrun lọna igba eleyii yoo si tun pọ sii lọjọ iwaju. | Nigeria population: Buhari tako ọmọ bẹẹrẹ òṣì bẹẹrẹ ní Nàìjíríà, ó ṣàgbékalẹ̀ ètò láti dẹ́kun rẹ̀ Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe agbekalẹ eto ti yoo ṣe adinku ọmọ bẹẹrẹ oṣi bẹẹrẹ lorilẹede Naijiria. Buhari to ṣe agbekalẹ eto naa niluu Abuja sọ pe o ṣe pataki bayii lati mu ifeto sọmọ bibi lọkunkundun. Buhari tun ṣe agbekalẹ eto mii ti yoo ṣe iranwọ lori ati dẹkun bi awọn eeyan ṣe n pọ sii ni Naijiria. Buhari ṣe agbekalẹ eto ifeto sọmọ bibi Aarẹ Buhari ṣalaye pe ohun to bi eto ifeto sọmọ bibi wa ni lati mu ibayegbadun ba awọn ọmọ Naijiria. Buhari ni eyi wa lara awọn eto ijọba ẹgbẹ oṣelu APC to wa lode bayii. Eto yii yoo ṣe iranwọ lori bi adinku yoo ṣe ba bi ọpọ eeyan ṣe n bi ọmọ silẹ lọpọ yanturu. Ara awọn ọna ti ijọba fẹ gba lati ṣe eto ọhun ni nipa ilanilọyẹ lori ifeto sọmọ bibi. Aarẹ Buhari gbagbọ pe eto yii yoo ran ọpọ eeyan lọwọ lati fi alafao si aarin awọn ọmọ wọn. Buhari kọminu lori bi Naijiria ṣe pọ julọ l'Afrika Aarẹ Buhari ni orilẹede naijiria lo pọ julọ nilẹ Afirika nigba to tun jẹ orilẹede to wa ni ipo keje lagbaye. Buhari ni Naijiria wa lara awọn orilẹede diẹ lagbaaye to ni ọdọ julọ. Aarẹ ni ida mejilelaadọrin ninu ọgọrun awọn ọdọ yii ni ọjọ ori wọn ko to ọgbọn ọdun. Bakan naa ni Buhari sọ pe idaji awọn obinrin ninu awọn ọdọ yii lo wa ni asiko ti wọn ṣe abiamọ tori ọjọ ori bẹrẹ lati ọdun mẹẹdogun si ọdun mọkadinlaadọta. Ọna abayọ si ọmọ bẹẹrẹ oṣi bẹẹrẹ Buhari ni ijọba ko ni dẹkun lilo eto ẹkọ to peye lati maa la awọn eeyan lọyẹ. Aarẹ ni eto ẹkọ yoo ṣe iranwọ papaa julọ fawọn obinrin to ba jẹ ọmọde tori awọn ni wọn le gboyun nigba kugba. Buhari tun sọ pe eto ikaniyan to n bọ yoo tun ṣe iranwọ lati mọ ọna lati mu adinku ba ọmọ bẹẹrẹ oṣi bẹẹrẹ. Ni bayii, akọsilẹ fihan pe eeyan to wa ni Naijiria le ni ẹgbẹrun lọna igba eleyii yoo si tun pọ sii lọjọ iwaju. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60226802 |
2health
| Pneumonia: Dókítà ní kòkòrò àìfojúrí ló ń fàá òtútù àyà | Ọpọ asọdun lo maa n waye nipa aisan kan ta n pe ni otutu aya eyi ti oloyinbo n pe ni Pneumonia. Koda, aisan yii wọpọ ni Naijiria, paapa laarin awọn ọmọde, ti ajọ Unicef si ti kede pe orilẹede Naijiria wa lara awọn ti aisan naa ti wọpọ lagbaye. Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Onisegun oyinbo kan, Dokita Afeez Oladele ni aisan otutu aya ko ni ohunkohun se pẹlu otutu rara nitori eeyan lee sun si ori ilẹ lasan tabi si aya si ẹrọ amuletutu lai wọ asọ, ti onitọun ko si ni ni otutu aya rara. O ni awọn kokoro kan ti a ko lee fi oju ri lo n fa aisan naa, ti a si lee ko awọn kokoro kekeke naa latinu afẹfẹ buruku, eefin, eedu, tabi ka lo ife ati ifọyin ẹni to ba ni aisan naa. O wa gba awọn obi nimọran lati maa tete gbe awọn ọmọde ti wọn ba kẹẹfin pe o n hu ikọ lọ sile iwosan fun itọju, ki aisan naa to bọwọ sori. | Pneumonia: Dókítà ní kòkòrò àìfojúrí ló ń fàá òtútù àyà Ọpọ asọdun lo maa n waye nipa aisan kan ta n pe ni otutu aya eyi ti oloyinbo n pe ni Pneumonia. Koda, aisan yii wọpọ ni Naijiria, paapa laarin awọn ọmọde, ti ajọ Unicef si ti kede pe orilẹede Naijiria wa lara awọn ti aisan naa ti wọpọ lagbaye. Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Onisegun oyinbo kan, Dokita Afeez Oladele ni aisan otutu aya ko ni ohunkohun se pẹlu otutu rara nitori eeyan lee sun si ori ilẹ lasan tabi si aya si ẹrọ amuletutu lai wọ asọ, ti onitọun ko si ni ni otutu aya rara. O ni awọn kokoro kan ti a ko lee fi oju ri lo n fa aisan naa, ti a si lee ko awọn kokoro kekeke naa latinu afẹfẹ buruku, eefin, eedu, tabi ka lo ife ati ifọyin ẹni to ba ni aisan naa. O wa gba awọn obi nimọran lati maa tete gbe awọn ọmọde ti wọn ba kẹẹfin pe o n hu ikọ lọ sile iwosan fun itọju, ki aisan naa to bọwọ sori. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-50509486 |
1entertainment
| Yomi Fabiyi Oko Iyabo: Ẹgbẹ́ TAMPAN ti dá Yomi Fabiyi dúró lẹ́yìn tó gbé fíímù Oko Iyabo jáde | Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe apapọ ẹgbẹ awọn oṣere tiata ni Naijiria, TAMPAN ti fofin de Yomi Fabiyi pe ko lọ rọọkun nile na. Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita lọjọ Ẹti lo ti kede pe igbesẹ naa waye nitori iwa abuku ati eyi ti ko ba oju mu gẹgẹ bi oṣere ti Fabiyi hu nipa fiimu Ọkọ Iyabọ to gbe jade laipẹ yii. Fiimu naa to gbe jade ni ọjọ Aiku to kọja da lori ọrọ ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan osẹre miran, Baba Ijesha. TAMPAN sọ pe igbesẹ naa waye lẹyin ti oun gbọ awijare Yomi Fabiyi to jẹ olukọtan, olootu ati oludari fiimu naa, ati oludari keji, Ọgbẹni Dele Matti. "A ri pe wọn jẹbi hihu iwa ti ko bojumu fun akọṣẹmọṣẹ oni tiata. Awọn alaṣẹ TAMPAN sọ pe botilẹ jẹ pe Ọgbẹni Fabiyi taku pe ẹtọ oun gẹgẹ bi eniyan, ni lati gbe fiimu jade, eyi ti yoo sọ bi nakn ṣe ri gan-an lori iṣẹlẹ ọrọ Baba Ijesha, wọn ni alajọṣiṣẹpọ rẹ gba pe oun jẹbi, to si kabamọ ipa to ko ninu ṣiṣe fiimu naa. Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi si ori Instagram rẹ ni ikede naa ti jade. Awọn abajade iwadii ati idajọ ẹgbẹ TAMPAN nipa Yomi Fabiyi: Ọgbẹni Yomi Fabiyi mọọmọ ṣe fiimu naa lai bọwọ fun ilana to de fiimu ṣiṣe, eyi to tumọ si pe o sẹ isẹ naa pẹlu erongba lati da wahala silẹ laarin ilu. Ti iṣẹ naa (fiimu) kii ba ti i ṣe ti ile Sinima, ẹnikẹni ko ni ẹtọ lati lo orukọ eeyan ti iṣẹlẹ ṣẹlẹ si ninu fiimu. "Nitori naa, iwa aibikita ni bi Fabiyi ṣe lo orukọ, ati awọn iṣẹlẹ to waye loju aye, lai gba aṣẹ lọwọ awọn ti ọrọ kan. Ìtàn, agbekalẹ itan, ohùn, ọrọ, akori, orukọ, ati gbogbo nkan to nii sẹ pẹlu fiimu "Ọkọ Iyabọ" jẹ awsn nkan to ṣẹlẹ, eleyi to le mu ki ojuṣaaju waye lori ẹjọ naa to ti wa ni ile ẹjọ. Iwa aibikiti to hu ti tabuku si orukọ ẹgbẹ wa. Ẹni ti wọn jọ dari ere naa, Ọgbẹni Dele Matti, ti fihan pe oun jẹbi, o ti ronu piwada, a si daa duro fun oṣu mẹta pere. A paṣẹ ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ wa to kopa ninu fiimu naa yọju siwaju igbimọ to wa fun yiyanju aawọ ati ilana isẹ wa, ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje, ọdun2021. Lakotan, ẹgbẹ TAMPAN sọ pe ẹgbẹ awọn eeyan to jẹ ọmọluabi ni oun, ti ko si ni ṣe atilẹyin fun ohunkohun to ba le da wahala silẹ ni awujọ. | Yomi Fabiyi Oko Iyabo: Ẹgbẹ́ TAMPAN ti dá Yomi Fabiyi dúró lẹ́yìn tó gbé fíímù Oko Iyabo jáde Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe apapọ ẹgbẹ awọn oṣere tiata ni Naijiria, TAMPAN ti fofin de Yomi Fabiyi pe ko lọ rọọkun nile na. Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita lọjọ Ẹti lo ti kede pe igbesẹ naa waye nitori iwa abuku ati eyi ti ko ba oju mu gẹgẹ bi oṣere ti Fabiyi hu nipa fiimu Ọkọ Iyabọ to gbe jade laipẹ yii. Fiimu naa to gbe jade ni ọjọ Aiku to kọja da lori ọrọ ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan osẹre miran, Baba Ijesha. TAMPAN sọ pe igbesẹ naa waye lẹyin ti oun gbọ awijare Yomi Fabiyi to jẹ olukọtan, olootu ati oludari fiimu naa, ati oludari keji, Ọgbẹni Dele Matti. "A ri pe wọn jẹbi hihu iwa ti ko bojumu fun akọṣẹmọṣẹ oni tiata. Awọn alaṣẹ TAMPAN sọ pe botilẹ jẹ pe Ọgbẹni Fabiyi taku pe ẹtọ oun gẹgẹ bi eniyan, ni lati gbe fiimu jade, eyi ti yoo sọ bi nakn ṣe ri gan-an lori iṣẹlẹ ọrọ Baba Ijesha, wọn ni alajọṣiṣẹpọ rẹ gba pe oun jẹbi, to si kabamọ ipa to ko ninu ṣiṣe fiimu naa. Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi si ori Instagram rẹ ni ikede naa ti jade. Awọn abajade iwadii ati idajọ ẹgbẹ TAMPAN nipa Yomi Fabiyi: Ọgbẹni Yomi Fabiyi mọọmọ ṣe fiimu naa lai bọwọ fun ilana to de fiimu ṣiṣe, eyi to tumọ si pe o sẹ isẹ naa pẹlu erongba lati da wahala silẹ laarin ilu. Ti iṣẹ naa (fiimu) kii ba ti i ṣe ti ile Sinima, ẹnikẹni ko ni ẹtọ lati lo orukọ eeyan ti iṣẹlẹ ṣẹlẹ si ninu fiimu. "Nitori naa, iwa aibikita ni bi Fabiyi ṣe lo orukọ, ati awọn iṣẹlẹ to waye loju aye, lai gba aṣẹ lọwọ awọn ti ọrọ kan. Ìtàn, agbekalẹ itan, ohùn, ọrọ, akori, orukọ, ati gbogbo nkan to nii sẹ pẹlu fiimu "Ọkọ Iyabọ" jẹ awsn nkan to ṣẹlẹ, eleyi to le mu ki ojuṣaaju waye lori ẹjọ naa to ti wa ni ile ẹjọ. Iwa aibikiti to hu ti tabuku si orukọ ẹgbẹ wa. Ẹni ti wọn jọ dari ere naa, Ọgbẹni Dele Matti, ti fihan pe oun jẹbi, o ti ronu piwada, a si daa duro fun oṣu mẹta pere. A paṣẹ ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ wa to kopa ninu fiimu naa yọju siwaju igbimọ to wa fun yiyanju aawọ ati ilana isẹ wa, ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje, ọdun2021. Lakotan, ẹgbẹ TAMPAN sọ pe ẹgbẹ awọn eeyan to jẹ ọmọluabi ni oun, ti ko si ni ṣe atilẹyin fun ohunkohun to ba le da wahala silẹ ni awujọ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57783258 |
4religion
| Sotitobire: Ìdájọ́ òdòdò ló fẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Pásítọ̀ Sotitobire - Agbẹjọ́rò fún ìjọba | Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni ile ẹjọ giga ti ijọba ipinlẹ Ondo dajọ ẹwọn gbere fun Alfa Babatunde, to jẹ oludasilẹ ijọ Sotitobire Praising Chapel, ati awọn ọmọ ijọ rẹ marun, ti wọn fi ẹsun kan pe wọn lọwọ si bi ọmọ ọdun kan, Gold Kolawole ṣe di awati ninu ijọ naa ni ọdun 2019. Bo tilẹ jẹ pe agbẹjọro fun ijọba ipinlẹ Ondo lori ẹjọ naa, Adekola Olawoye, sọ pe idajọ ododo lo waye lori ọrọ naa, nitori pe "bi irọ ba lọ logun ọdun, ọjọ kan ni otitọ yoo ba". Amọ agbẹjọro to ṣoju awọn olujẹjọ, Akinyemi Omoware, sọ fun BBC pe awọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ ile ẹjọ giga ọhun. Mi ò fẹ́ di ọlọ́lá jùlọ tí mo bá di gómìnà Ondo, màá tẹ̀lé ìfẹ́ aráàlù póńbélé - Ojon YPP Ojú àwọn èèyàn Ondo ti là pé ìnira ni ẹgbẹ́ APC mú wá - Jegede PDP Àwọn kan ṣónú bí wọ́n bá di gómìnà, ẹ fún wa láyè láti wá parí iṣẹ́ táa bẹ̀rẹ̀ - Akeredolu 'N500 dé fún gbogbo ọmọ tuntun lóṣooṣù bí mo bá di gómìnà Ondo - Adeleye AAC | Sotitobire: Ìdájọ́ òdòdò ló fẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Pásítọ̀ Sotitobire - Agbẹjọ́rò fún ìjọba Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni ile ẹjọ giga ti ijọba ipinlẹ Ondo dajọ ẹwọn gbere fun Alfa Babatunde, to jẹ oludasilẹ ijọ Sotitobire Praising Chapel, ati awọn ọmọ ijọ rẹ marun, ti wọn fi ẹsun kan pe wọn lọwọ si bi ọmọ ọdun kan, Gold Kolawole ṣe di awati ninu ijọ naa ni ọdun 2019. Bo tilẹ jẹ pe agbẹjọro fun ijọba ipinlẹ Ondo lori ẹjọ naa, Adekola Olawoye, sọ pe idajọ ododo lo waye lori ọrọ naa, nitori pe "bi irọ ba lọ logun ọdun, ọjọ kan ni otitọ yoo ba". Amọ agbẹjọro to ṣoju awọn olujẹjọ, Akinyemi Omoware, sọ fun BBC pe awọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ ile ẹjọ giga ọhun. Mi ò fẹ́ di ọlọ́lá jùlọ tí mo bá di gómìnà Ondo, màá tẹ̀lé ìfẹ́ aráàlù póńbélé - Ojon YPP Ojú àwọn èèyàn Ondo ti là pé ìnira ni ẹgbẹ́ APC mú wá - Jegede PDP Àwọn kan ṣónú bí wọ́n bá di gómìnà, ẹ fún wa láyè láti wá parí iṣẹ́ táa bẹ̀rẹ̀ - Akeredolu 'N500 dé fún gbogbo ọmọ tuntun lóṣooṣù bí mo bá di gómìnà Ondo - Adeleye AAC | https://www.bbc.com/yoruba/54447371 |
3politics
| Yemi Osinbajo: Èrò ọmọ Nàíjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ìkéde Osinbajo láti dupò ààrẹ Nàìjíríà | Lowurọ ọjọ Aje, ọjọ kọkanla ọdun 2022, ni igbakeji aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ, fun gbogbo aye. Eyi si ti fa ọpọlọpọ itakurọsọ lori ayelujara ati lagbo ijiroro ọrọ oṣelu gbogbo. Kii ṣe ikede rẹ gan an lo n fa awuyewuye nitori ọpọlọpọ lo wulẹ ti n reti pe yoo ri bẹẹ. Amọṣa, ohun to n fa ariyanjiyan lori rẹ ko ju bi ọrọ naa yoo ṣe ja si laarin igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo pẹlu Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu to jẹ ọga rẹ tẹlẹ. Bi awọn kan ṣe n sọ pe ko yẹ ki erin fọn ki ọmọ rẹ naa tun fọn; lawọn miran n woye pe ko si bi ọbọ ṣe ṣe ori ti inaki ko ṣe o. 'N ṣe lo yẹ ki Tinubu gba adura pe ki Osinbajo ju oun lọ gẹgẹ bii baba si ọmọ - Igun Osinbajo sọrọ Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba, Amofin Kayọde Ajulọ to jẹ gbajumọ amofin, ajafẹtọ araalu to tun jẹ alabaṣepọ Igbakeji aarẹ Muhammadu Buhari ni igbesẹ ti ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ti n reti ni igbesẹ ti Osinbajo gbe naa. O ṣalaye pe idi ti igbesẹ ati kede erongba rẹ ṣe pẹ bayii ko to jade ko ju wi pe igbakeji aarẹ Naijiria naa nilo asiko lati forikori pẹlawọn eekan gbogbo kaakiri lati lee mọ ibi ti yoo gbe ọrọ gba. Lori boya ọrọ naa ko ni fara jọ ẹsun ọdalẹ ti awọn eeyan kan fi n kan igbakeji aarẹ pẹlu bi o ṣe fẹ dije tako Tinubu, ti ọpọ woye gẹgẹ bii oloore rẹ ni. Amofin Ajulọ ṣalaye pe, ni ilẹ Yoruba, gbogbo obi lo maa n gbadura ki ọmọ wọn ju awọn lọ. O darukọ awọn eekan ilẹ Yoruba bii Baba Abraham Adesanya, Baba Daodu, Baba Ayọ Adebanjọ ati Mama Abibatu Mọgaji maa n gba fun Aṣiwaju nigba naa ni pe yoo ga ju wọn lọ , to si ri bẹẹ. "Adura to yẹ ki aṣiwaju maa gba bayii fun Osinbajo bayii naa ni pe iwọ ọmọ mi o waa ga ju mi lọ." Ọrọ yii dabi ọmọ to fẹ ba baba rẹ du iyawo ni - Igun Tinubu ero rẹ Ninu ọrọ tirẹ, Abdulhakeen Adegoke, adari ẹgbẹ Yoruba Welfare Group ṣalaye fun BBC News yoruba pe ohun ti ko yẹ ko waye ni ikede erongba igbakeji aarẹ Osinbajo pe oun naa fẹ dije lẹyin ti ẹni ti a lee pe ni ọga ọga rẹ ti bọ si gbangba lati sọ pe oun fẹ dije fun ipo naa. Abdulhakeen Adegoke ni osibajo ti ṣi ẹsẹ gbe lori igbesẹ naa nitori ko si bi igbesẹ rẹ ko ṣe ni di igbesẹ Yoruba lati di aarẹ lowo ati pe ni iwoye toun o, itanje lasan lawon eekan ni apap ariwa Naijiria n fun un ti wọn n sọ oe awọn wa lẹyin. O wa rọ awọn agbagba Yoruba lati pe ajọ to nironu fun yiyanju ọrọ ọhun ki alaafia lee jọba laaarin awọn mejeeji. To ba jẹ pe ṣaaju igba ti Aṣiwaju kede tirẹ ni Osinbajo ti kede ni, ọpọ gan ni yoo maa rọ aṣiwaju pe ko sinmi naa ki ọmọ rẹ, iyẹn Aṣiwaju Osinbajo lee dije. "Ọrọ yii dabi ọmọ to fẹ ba baba to bii du iyawo. Ki awọn baba wa nilẹ Yoruba tete pe aro ati ọdọfin inu wa silẹ." Owurọ ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ni igbakeji aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ, fun gbogbo aye. Osinbajo ninu fidio kan to fi si oju opo Twitter rẹ lo ti kede igbesẹ naa. Eyi waye lẹyin to ti kọkọ kede fun awọn gomina kan to wa ninu ẹgbẹ osẹlu All Progressives Congress, APC, lọjọ Aiku. Igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo ti kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ Naijiria ninu eto idibo ọdun 2023. Osinbajo ninu fidio kan to fi si oju opo Twitter rẹ ni owurọ ọjọ Aje lo ti sisọ loju eegun pe oun maa dije fun ipo aarẹ. Osinbajo ni "Pẹlu irẹlẹ ọkan ni mo fi n kede erongba mi lati dije fun ipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oselu APC. A maa mu ẹkunrẹrẹ awọn koko ọrọ to sọ nipa erongba rẹ lati dije naa wa fun yin laipẹ. saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe lẹyin ọpọlọpọ akoko ijiroro ati ifikuluku, o dabi ẹni pe igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo ti ṣetan bayii lẹyin o rẹyin lati dije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria ldun 2023. Kii ṣe iroyin abẹnu mọ pe oniruuru ẹgbẹ, ọgba ati igun lo ti bọ sigboro lati gbe lẹyin agba amofin naa pe ki oun pẹlu darapọ mọ awọn oloṣelu to fẹ dije fun aṣia ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo aarẹ lorilẹede Naijiria. Ni oṣu karun un ọdun 2022 ni eto idibo lati mọ ẹni ti ẹgbẹ oṣelu APC yoo fa kalẹ fun idije ipo aarẹ lasiko idibo apapọ ọdun 2023 yoo waye. Gẹgẹ bi awọn iroyin kan to jade lati ile aarẹ, Aso Rock Villa nilu Abuja lọjọ Aiku ṣe sọ, igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria naa ti bun awọn gomina bii mejila kan gbọ nipa erongba rẹ lati dije. Iroyin naa sọ pe, Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo fi to awọn gomina naa ninu eyi ti Nasir El-Rufai (Kaduna), Dapo Abiodun (Ogun), Abdullahi Sule (Nasarawa), Babagana Zulum (Borno) ati Babajide Sanwo-Olu (Eko) leti lasiko apejẹ iṣinu awẹ Ramadan, Iftar to pe nibi to ti jẹ ko di mimọ fawọn gomina naa nipa erongba rẹ lati tẹsiwaju pẹlu iṣẹ ti ọga rẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ba ṣe ku lasiko ti saa iṣejọba rẹ ba pari ldun 2023. Bọla Tinubu jẹ ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC, ohun si ni gomina ipinlẹ Eko laarin ọdun 199 si 2007. Okorocha ni gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, igba akọkọ rẹ si kọ niyi lati dije, lẹyin to ti kọkọ gbe igba ibo fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu AA nigba kan ri. Rochas Okorocha fi erongba rẹ lati dije han ninu lẹta kan to kọ ranṣẹ si aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Ahmad Lawan lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kini ọdun 2022. Oun ni obinrin akọkọ to jade lati kede pe oun fẹ dije fun ipo aarẹ lọdun 2023. Ko tii kede ẹgbẹ oṣelu kankan ti o wa bayii na. Ohun to sọ ni pe ẹgbẹ oṣelu to ba ni iran kan naa pẹlu oun loun yoo ba lọ. loṣu kẹta ọdun 2023 ni Dele Mọmọdu kede pe oun naa yoo dije ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP. Igba akọkọ kọ niyi ti Dele Mọmọdu yoo maa fifẹhan si didije fun ipo aarẹ ni Naijiria. Yahaya Bello ni gomina ipinlẹ Kogi lọwọ yii. Laipẹ yii loun pẹlu kede pe oun naa nifẹ si ipo aarẹ lọdun 2023. Awọn miran to tun ti gbe igbesẹ yii kan naa ni aarẹ ile aṣofin agba tẹlẹ ri, Dokita Bukọla Saraki, alaga igbimọ awọn gomina lorilẹede Naijiria, NGF to tun jẹ gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, minisita fọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Dokita Chris Ngige ati bẹẹ lọ. | Yemi Osinbajo: Èrò ọmọ Nàíjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ìkéde Osinbajo láti dupò ààrẹ Nàìjíríà Lowurọ ọjọ Aje, ọjọ kọkanla ọdun 2022, ni igbakeji aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ, fun gbogbo aye. Eyi si ti fa ọpọlọpọ itakurọsọ lori ayelujara ati lagbo ijiroro ọrọ oṣelu gbogbo. Kii ṣe ikede rẹ gan an lo n fa awuyewuye nitori ọpọlọpọ lo wulẹ ti n reti pe yoo ri bẹẹ. Amọṣa, ohun to n fa ariyanjiyan lori rẹ ko ju bi ọrọ naa yoo ṣe ja si laarin igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo pẹlu Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu to jẹ ọga rẹ tẹlẹ. Bi awọn kan ṣe n sọ pe ko yẹ ki erin fọn ki ọmọ rẹ naa tun fọn; lawọn miran n woye pe ko si bi ọbọ ṣe ṣe ori ti inaki ko ṣe o. 'N ṣe lo yẹ ki Tinubu gba adura pe ki Osinbajo ju oun lọ gẹgẹ bii baba si ọmọ - Igun Osinbajo sọrọ Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba, Amofin Kayọde Ajulọ to jẹ gbajumọ amofin, ajafẹtọ araalu to tun jẹ alabaṣepọ Igbakeji aarẹ Muhammadu Buhari ni igbesẹ ti ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ti n reti ni igbesẹ ti Osinbajo gbe naa. O ṣalaye pe idi ti igbesẹ ati kede erongba rẹ ṣe pẹ bayii ko to jade ko ju wi pe igbakeji aarẹ Naijiria naa nilo asiko lati forikori pẹlawọn eekan gbogbo kaakiri lati lee mọ ibi ti yoo gbe ọrọ gba. Lori boya ọrọ naa ko ni fara jọ ẹsun ọdalẹ ti awọn eeyan kan fi n kan igbakeji aarẹ pẹlu bi o ṣe fẹ dije tako Tinubu, ti ọpọ woye gẹgẹ bii oloore rẹ ni. Amofin Ajulọ ṣalaye pe, ni ilẹ Yoruba, gbogbo obi lo maa n gbadura ki ọmọ wọn ju awọn lọ. O darukọ awọn eekan ilẹ Yoruba bii Baba Abraham Adesanya, Baba Daodu, Baba Ayọ Adebanjọ ati Mama Abibatu Mọgaji maa n gba fun Aṣiwaju nigba naa ni pe yoo ga ju wọn lọ , to si ri bẹẹ. "Adura to yẹ ki aṣiwaju maa gba bayii fun Osinbajo bayii naa ni pe iwọ ọmọ mi o waa ga ju mi lọ." Ọrọ yii dabi ọmọ to fẹ ba baba rẹ du iyawo ni - Igun Tinubu ero rẹ Ninu ọrọ tirẹ, Abdulhakeen Adegoke, adari ẹgbẹ Yoruba Welfare Group ṣalaye fun BBC News yoruba pe ohun ti ko yẹ ko waye ni ikede erongba igbakeji aarẹ Osinbajo pe oun naa fẹ dije lẹyin ti ẹni ti a lee pe ni ọga ọga rẹ ti bọ si gbangba lati sọ pe oun fẹ dije fun ipo naa. Abdulhakeen Adegoke ni osibajo ti ṣi ẹsẹ gbe lori igbesẹ naa nitori ko si bi igbesẹ rẹ ko ṣe ni di igbesẹ Yoruba lati di aarẹ lowo ati pe ni iwoye toun o, itanje lasan lawon eekan ni apap ariwa Naijiria n fun un ti wọn n sọ oe awọn wa lẹyin. O wa rọ awọn agbagba Yoruba lati pe ajọ to nironu fun yiyanju ọrọ ọhun ki alaafia lee jọba laaarin awọn mejeeji. To ba jẹ pe ṣaaju igba ti Aṣiwaju kede tirẹ ni Osinbajo ti kede ni, ọpọ gan ni yoo maa rọ aṣiwaju pe ko sinmi naa ki ọmọ rẹ, iyẹn Aṣiwaju Osinbajo lee dije. "Ọrọ yii dabi ọmọ to fẹ ba baba to bii du iyawo. Ki awọn baba wa nilẹ Yoruba tete pe aro ati ọdọfin inu wa silẹ." Owurọ ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ni igbakeji aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ, fun gbogbo aye. Osinbajo ninu fidio kan to fi si oju opo Twitter rẹ lo ti kede igbesẹ naa. Eyi waye lẹyin to ti kọkọ kede fun awọn gomina kan to wa ninu ẹgbẹ osẹlu All Progressives Congress, APC, lọjọ Aiku. Igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo ti kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ Naijiria ninu eto idibo ọdun 2023. Osinbajo ninu fidio kan to fi si oju opo Twitter rẹ ni owurọ ọjọ Aje lo ti sisọ loju eegun pe oun maa dije fun ipo aarẹ. Osinbajo ni "Pẹlu irẹlẹ ọkan ni mo fi n kede erongba mi lati dije fun ipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oselu APC. A maa mu ẹkunrẹrẹ awọn koko ọrọ to sọ nipa erongba rẹ lati dije naa wa fun yin laipẹ. saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe lẹyin ọpọlọpọ akoko ijiroro ati ifikuluku, o dabi ẹni pe igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo ti ṣetan bayii lẹyin o rẹyin lati dije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria ldun 2023. Kii ṣe iroyin abẹnu mọ pe oniruuru ẹgbẹ, ọgba ati igun lo ti bọ sigboro lati gbe lẹyin agba amofin naa pe ki oun pẹlu darapọ mọ awọn oloṣelu to fẹ dije fun aṣia ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo aarẹ lorilẹede Naijiria. Ni oṣu karun un ọdun 2022 ni eto idibo lati mọ ẹni ti ẹgbẹ oṣelu APC yoo fa kalẹ fun idije ipo aarẹ lasiko idibo apapọ ọdun 2023 yoo waye. Gẹgẹ bi awọn iroyin kan to jade lati ile aarẹ, Aso Rock Villa nilu Abuja lọjọ Aiku ṣe sọ, igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria naa ti bun awọn gomina bii mejila kan gbọ nipa erongba rẹ lati dije. Iroyin naa sọ pe, Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo fi to awọn gomina naa ninu eyi ti Nasir El-Rufai (Kaduna), Dapo Abiodun (Ogun), Abdullahi Sule (Nasarawa), Babagana Zulum (Borno) ati Babajide Sanwo-Olu (Eko) leti lasiko apejẹ iṣinu awẹ Ramadan, Iftar to pe nibi to ti jẹ ko di mimọ fawọn gomina naa nipa erongba rẹ lati tẹsiwaju pẹlu iṣẹ ti ọga rẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ba ṣe ku lasiko ti saa iṣejọba rẹ ba pari ldun 2023. Bọla Tinubu jẹ ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC, ohun si ni gomina ipinlẹ Eko laarin ọdun 199 si 2007. Okorocha ni gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, igba akọkọ rẹ si kọ niyi lati dije, lẹyin to ti kọkọ gbe igba ibo fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu AA nigba kan ri. Rochas Okorocha fi erongba rẹ lati dije han ninu lẹta kan to kọ ranṣẹ si aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Ahmad Lawan lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kini ọdun 2022. Oun ni obinrin akọkọ to jade lati kede pe oun fẹ dije fun ipo aarẹ lọdun 2023. Ko tii kede ẹgbẹ oṣelu kankan ti o wa bayii na. Ohun to sọ ni pe ẹgbẹ oṣelu to ba ni iran kan naa pẹlu oun loun yoo ba lọ. loṣu kẹta ọdun 2023 ni Dele Mọmọdu kede pe oun naa yoo dije ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP. Igba akọkọ kọ niyi ti Dele Mọmọdu yoo maa fifẹhan si didije fun ipo aarẹ ni Naijiria. Yahaya Bello ni gomina ipinlẹ Kogi lọwọ yii. Laipẹ yii loun pẹlu kede pe oun naa nifẹ si ipo aarẹ lọdun 2023. Awọn miran to tun ti gbe igbesẹ yii kan naa ni aarẹ ile aṣofin agba tẹlẹ ri, Dokita Bukọla Saraki, alaga igbimọ awọn gomina lorilẹede Naijiria, NGF to tun jẹ gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, minisita fọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Dokita Chris Ngige ati bẹẹ lọ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61064215 |
5sports
| IAAF World Championships: Abiyamọ kan di lobìnrin tó leè sáré "100 meters" jùlọ l'àgbáyé | Obinrin ọmọ ọdun mejilelogun kan lati orilẹ-ede Jamaica ti wọ inu iwe itan gẹgẹ bi obinrin to lee sare ori papa oniwọn ẹsẹ ọgọrun un julọ l'agbaye. Shelly-Ann Fraser-Pryce to jẹ ọlọmọ kan tun ni ẹni to dagba ju l'gbaye to gba ife ẹyẹ naa lẹyin to gba ife wura ni idije agbaye to n lọ lọwọ ni Doha, lorilẹ-ede Qatar. Dalemoṣu yii lo sa ere ori papa naa larin iṣẹju mẹwaa o le diẹ, lati gba ife ẹlẹẹkẹjọ iru rẹ ti yoo gba. Lẹyin to gba ife ẹyẹ naa tan, o ni inu oun dun gidigidi. O ṣalaye siwaju sii pe, aṣiri aṣeyọri oun ni iwa irẹlẹ ti oun ni ati bi oun ṣe mu iṣẹ oun lokunkundun. Bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ awọn ololufe ere ori papa ni ko yọju lati wo Shelly-Ann ni igba to n sa ere naa, o ni oun ko bikita rara. Ṣaaju akoko yii ni Shelly-Ann ti kopa ninu awọn idije agbaye miran bii; idije Olympic ti Beijin lọdun 2008, idije agbaye Berlin lọdun 2009, idije Olympic ti Londo lọdun 2012, ati bẹẹbẹẹ lọ. | IAAF World Championships: Abiyamọ kan di lobìnrin tó leè sáré "100 meters" jùlọ l'àgbáyé Obinrin ọmọ ọdun mejilelogun kan lati orilẹ-ede Jamaica ti wọ inu iwe itan gẹgẹ bi obinrin to lee sare ori papa oniwọn ẹsẹ ọgọrun un julọ l'agbaye. Shelly-Ann Fraser-Pryce to jẹ ọlọmọ kan tun ni ẹni to dagba ju l'gbaye to gba ife ẹyẹ naa lẹyin to gba ife wura ni idije agbaye to n lọ lọwọ ni Doha, lorilẹ-ede Qatar. Dalemoṣu yii lo sa ere ori papa naa larin iṣẹju mẹwaa o le diẹ, lati gba ife ẹlẹẹkẹjọ iru rẹ ti yoo gba. Lẹyin to gba ife ẹyẹ naa tan, o ni inu oun dun gidigidi. O ṣalaye siwaju sii pe, aṣiri aṣeyọri oun ni iwa irẹlẹ ti oun ni ati bi oun ṣe mu iṣẹ oun lokunkundun. Bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ awọn ololufe ere ori papa ni ko yọju lati wo Shelly-Ann ni igba to n sa ere naa, o ni oun ko bikita rara. Ṣaaju akoko yii ni Shelly-Ann ti kopa ninu awọn idije agbaye miran bii; idije Olympic ti Beijin lọdun 2008, idije agbaye Berlin lọdun 2009, idije Olympic ti Londo lọdun 2012, ati bẹẹbẹẹ lọ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49898089 |
2health
| Coronavirus in Nigeria: Ǹjẹ́ ṣé òògùn apakòkòrò le pa ààrùn coronavirus? | Oriṣiiriṣii nnkan lawọn eeyan n sọ pe o le wo aarun coronavirus ti o ba gbogbo aye finra lọwọ. Laipẹ yii ni aarẹ orilẹede Amẹrika sọ oogun apakokoro pe o le wo aarun aarun coronavirus. Ko si ohun to jọ bẹẹ raa! Ajọ eto ilera lagbaye, WHO sọ pe iwadii si n lọ lọwọ lori ati wa oogun tabi abẹrẹ to le wo coronovirus ṣugbọn ko sii oogun rẹ bayii. Alaye lẹkunrẹrẹ fidio yii. | Coronavirus in Nigeria: Ǹjẹ́ ṣé òògùn apakòkòrò le pa ààrùn coronavirus? Oriṣiiriṣii nnkan lawọn eeyan n sọ pe o le wo aarun coronavirus ti o ba gbogbo aye finra lọwọ. Laipẹ yii ni aarẹ orilẹede Amẹrika sọ oogun apakokoro pe o le wo aarun aarun coronavirus. Ko si ohun to jọ bẹẹ raa! Ajọ eto ilera lagbaye, WHO sọ pe iwadii si n lọ lọwọ lori ati wa oogun tabi abẹrẹ to le wo coronovirus ṣugbọn ko sii oogun rẹ bayii. Alaye lẹkunrẹrẹ fidio yii. | https://www.bbc.com/yoruba/52416211 |
1entertainment
| Yoruba Films: Òṣèrè tíátà Muideen Oladapo gbàràdá lórí ètò 'Ṣé o láyà?' | Oṣere tiata Yoruba, Muideen Oladapo fihan lori eto BBC Yoruba, ''Ṣe o Laya'' pe oun laya gbangba. Bi o ti n dahun awọn ibeere ti wọn bi i, bẹẹ naa lo n ṣe atupalẹ idahun rẹ si awọn ibeere naa. Muideen fihan pe oun gbọ ede Yoruba daadaa gẹgẹ bi oṣere ere tiata Yoruba. | Yoruba Films: Òṣèrè tíátà Muideen Oladapo gbàràdá lórí ètò 'Ṣé o láyà?' Oṣere tiata Yoruba, Muideen Oladapo fihan lori eto BBC Yoruba, ''Ṣe o Laya'' pe oun laya gbangba. Bi o ti n dahun awọn ibeere ti wọn bi i, bẹẹ naa lo n ṣe atupalẹ idahun rẹ si awọn ibeere naa. Muideen fihan pe oun gbọ ede Yoruba daadaa gẹgẹ bi oṣere ere tiata Yoruba. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-52339308 |
1entertainment
| Mide Martins: Gbajúgbajà òṣèré ṣàlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí lóko sinimá | Kò sí iṣẹ́ tàbí òwò tí ènìyàn bá ń ṣe tí kò ní àwọn ewu tirẹ̀. Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Mide Martins Abiodun ti tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ ọ̀rọ̀ lórí ohun tí ojú rẹ̀ rí láìpẹ́ yìí nígbà tí ó ń ṣe sinimá rẹ̀ kan, Onitemi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. Mide Martins ṣàlàyé pé lásìkò tí òun ń ya abala eré náà lọ́wọ́ ni ẹsẹ̀ òun yẹ̀ gẹ̀rẹ̀, tí òun ṣubú, tí òun sì forí gbá táńgaran àlẹ̀mọ́lé ìyẹn táìsì (tiles). Ó ní òun fi orí gbá taisi naa gidigidi àti pé Ọlọ́run ló yọ òun tí òun kò fi pàdánù ọpọlọ lórí ìjàmbá náà tó wáyé. Bákan náà ló fi kun pé Ọlọ́run ló kó òun yọ, tí òun fóríbọ́ lọ́wọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò bá di ibá míì fún òun. Nígbà tó fi fọ́nrán kan nínú eré náà léde lórí ẹ̀rọ Instagram rẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ fún àtìlẹyìn tí wọ́n ṣe fún òun lórí sinimá náà. Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn laarin awọn osere tiata? Ní bí ọjọ́ mélòó sẹ́yìn ni Mide Martins fi fọ́nrán kan léde níbi tó ti ń sunkún nítorí pé ilé iṣẹ tó bá dòwòpọ̀ kọ̀ láti fi àwọn ibì kan nínú sinimá rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde sí inú fíìmù náà. Nínú fọ́nrán náà ló ti ṣàlàyé gbogbo àwọn ohun tó là kọjá láti ri dájú pé iṣẹ́ náà kẹ́sẹ járí. Ìyá Rainbow bú sígbé nígbà tó ń ṣeré lọ́wọ́ Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyìí tí àwọn òṣèré tíátà máa ń la ewu kọjá tàbí tí wọn yóò rí ìrírí tí yóò pa wọ́n lẹ́kún nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ òòjọ́ wọn. Yoruba ni ọrọ arokan nii fa ẹkun asunundakẹ wa nitori ẹkun lo n ba ikun wa, ọrọ lo si n ba moko moro wa. Nigba miran, ti ẹda ba si ro arokan, omije ni yoo maa ja bọ ni oju rẹ, o si le jẹ omije ayọ abi ti idakeji rẹ. Amọ ti ẹni to n ro arokan yii ba wa jẹ agbalagba, ti onitọ̀ọun si sadede maa wa ẹkun mu lairotẹlẹ, o ni ohun to ri. Bi ọrọ se jẹ ree pẹlu gbajumọ osere tiata kan, mama Idowu Phillips, ti ọpọ eeyan mọ si Mama Rainbow. Ọpọ osere tiata lo la ẹnu silẹ, lai le pa de mọ nigba ti Mama Rainbow bẹrẹ ẹkun alagbara yii. Oko ere tiata ni wọn wa, nibi ti wọn ti n ya sinima kan, ti wọn si fun iya agbalagba naa ni ojuse kan lati se. Mama Rainbow, ti yoo pe ẹni ọgọrin ọdun lọdun yii, ni wọn fun ni ojuse lati sun ẹkun ninu ere naa ni apa kan sinima ọhun. Amọ ọrọ naa kuro ni ere tabi awada nigba ti Mama Rainbow ko dakẹ ẹsun sisun, to si fi iriri igbe aye rẹ wọ inu ere to n se. Ojuse ti wọn fun naa lo se ni laanu pupọ, arokan ti Mama ro nipa ere naa, ati ọpọ ohun to sẹlẹ nile aye, ti oju rẹ ti ri si lo fa ẹkun asun un dakẹ naa wa. Ta ni Mide Martins? Gbajúgbajà òṣèré tíátà Yorùbá ní Mide Martins. Ó jẹ́ ọmọ bíbí gbajúgbajà òṣèré Funmi Martins tó di olóògbé lọdún 2002. Lẹ́yìn tí ìyá rẹ̀ papòdà ní Mide bẹ̀rẹ̀ eré tíátà láti ri pé orípa ìyá rẹ̀ kò parẹ́. Ní ọjọ́ kejìlá ọdún 1979 ni wọ́n bí Mide Martins. Ó fẹ́ adarí eré, Afeez Abiodun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Afeez ọwọ́ tí Ọlọ́run sì fi ọmọ ta wọ́n lọ́rẹ. | Mide Martins: Gbajúgbajà òṣèré ṣàlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí lóko sinimá Kò sí iṣẹ́ tàbí òwò tí ènìyàn bá ń ṣe tí kò ní àwọn ewu tirẹ̀. Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Mide Martins Abiodun ti tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ ọ̀rọ̀ lórí ohun tí ojú rẹ̀ rí láìpẹ́ yìí nígbà tí ó ń ṣe sinimá rẹ̀ kan, Onitemi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. Mide Martins ṣàlàyé pé lásìkò tí òun ń ya abala eré náà lọ́wọ́ ni ẹsẹ̀ òun yẹ̀ gẹ̀rẹ̀, tí òun ṣubú, tí òun sì forí gbá táńgaran àlẹ̀mọ́lé ìyẹn táìsì (tiles). Ó ní òun fi orí gbá taisi naa gidigidi àti pé Ọlọ́run ló yọ òun tí òun kò fi pàdánù ọpọlọ lórí ìjàmbá náà tó wáyé. Bákan náà ló fi kun pé Ọlọ́run ló kó òun yọ, tí òun fóríbọ́ lọ́wọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò bá di ibá míì fún òun. Nígbà tó fi fọ́nrán kan nínú eré náà léde lórí ẹ̀rọ Instagram rẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ fún àtìlẹyìn tí wọ́n ṣe fún òun lórí sinimá náà. Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn laarin awọn osere tiata? Ní bí ọjọ́ mélòó sẹ́yìn ni Mide Martins fi fọ́nrán kan léde níbi tó ti ń sunkún nítorí pé ilé iṣẹ tó bá dòwòpọ̀ kọ̀ láti fi àwọn ibì kan nínú sinimá rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde sí inú fíìmù náà. Nínú fọ́nrán náà ló ti ṣàlàyé gbogbo àwọn ohun tó là kọjá láti ri dájú pé iṣẹ́ náà kẹ́sẹ járí. Ìyá Rainbow bú sígbé nígbà tó ń ṣeré lọ́wọ́ Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyìí tí àwọn òṣèré tíátà máa ń la ewu kọjá tàbí tí wọn yóò rí ìrírí tí yóò pa wọ́n lẹ́kún nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ òòjọ́ wọn. Yoruba ni ọrọ arokan nii fa ẹkun asunundakẹ wa nitori ẹkun lo n ba ikun wa, ọrọ lo si n ba moko moro wa. Nigba miran, ti ẹda ba si ro arokan, omije ni yoo maa ja bọ ni oju rẹ, o si le jẹ omije ayọ abi ti idakeji rẹ. Amọ ti ẹni to n ro arokan yii ba wa jẹ agbalagba, ti onitọ̀ọun si sadede maa wa ẹkun mu lairotẹlẹ, o ni ohun to ri. Bi ọrọ se jẹ ree pẹlu gbajumọ osere tiata kan, mama Idowu Phillips, ti ọpọ eeyan mọ si Mama Rainbow. Ọpọ osere tiata lo la ẹnu silẹ, lai le pa de mọ nigba ti Mama Rainbow bẹrẹ ẹkun alagbara yii. Oko ere tiata ni wọn wa, nibi ti wọn ti n ya sinima kan, ti wọn si fun iya agbalagba naa ni ojuse kan lati se. Mama Rainbow, ti yoo pe ẹni ọgọrin ọdun lọdun yii, ni wọn fun ni ojuse lati sun ẹkun ninu ere naa ni apa kan sinima ọhun. Amọ ọrọ naa kuro ni ere tabi awada nigba ti Mama Rainbow ko dakẹ ẹsun sisun, to si fi iriri igbe aye rẹ wọ inu ere to n se. Ojuse ti wọn fun naa lo se ni laanu pupọ, arokan ti Mama ro nipa ere naa, ati ọpọ ohun to sẹlẹ nile aye, ti oju rẹ ti ri si lo fa ẹkun asun un dakẹ naa wa. Ta ni Mide Martins? Gbajúgbajà òṣèré tíátà Yorùbá ní Mide Martins. Ó jẹ́ ọmọ bíbí gbajúgbajà òṣèré Funmi Martins tó di olóògbé lọdún 2002. Lẹ́yìn tí ìyá rẹ̀ papòdà ní Mide bẹ̀rẹ̀ eré tíátà láti ri pé orípa ìyá rẹ̀ kò parẹ́. Ní ọjọ́ kejìlá ọdún 1979 ni wọ́n bí Mide Martins. Ó fẹ́ adarí eré, Afeez Abiodun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Afeez ọwọ́ tí Ọlọ́run sì fi ọmọ ta wọ́n lọ́rẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60744565 |
3politics
| Ìlera Nnamdi Kanu ń burú si, àìsàn ń ṣe é láti inú - Agbẹjọ́rò | Ifeanyi Ejiofor agbẹjọro fun adari ikọ ajijagbara IPOB, Nnamdi Kanu, ti sọrọ sita lori ilera onibara rẹ lẹyin to lugbadi arun miiran. Ejiofor, ninu atẹjade to fi ransẹ sita fawọn akọroyin lọjọ Aje ni onibara oun ni arun to n se eeyan ni inu ati ẹnu, ti oloyinbo pe ni Gastrointestinal Distorder. O ni eyi to mu ki aya ma ta Kanu ni ọpọ igba. O tẹsiwaju pe ileẹjọ giga to wa niluu Abuja labẹ isakoso Adajọ Binta Nyako, palasẹ fun ajọ DSS lati pese ilera to peye fun Nnamdi Kanu sugbọn wọn kọ. O wa ke gbajawire sita lẹyin to ṣe abẹwo si adari IPOB naa ni ọọfisi awọn DSS niluu Abuja lọjọ Ajẹ. “Ni bayi, Nnamdi Kanu n jẹ irora nitori aisan yii, ti o si nilo itọju ni kiakia. “Sugbọn o ṣe ni laanu pe ajọ DSS ko fun ni anfani lati ṣe itọju ara ẹ. “Kete ti a gbọ, ni agbẹjọro agba wa Oloye Mike Ozekhome pasẹ pe ki a bẹrẹ isẹ lati fi ofin si ifiyajẹni naa. Igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ, Olabode George ti fi aidunnu rẹ han si bi ẹgbẹ oṣelu PDP ko ṣe ni nkan gboogi lati fi dije dupo ni ilẹ Yoruba ni idibo ọdun to n bọ. Ninu ọrọ rẹ lori eto tẹlifiṣọn Arise TV lo ti fi ero rẹ han. Bode George ni ẹgbẹ oṣelu PDP ko dabi ẹgbẹ oṣelu APC to jẹ pe iha Guusu Naijiria ni wọn ti mu ẹni ti yoo dije du ipo aarẹ ni Naijiria ni idibo ọdun to n bọ. Bio tilẹ jẹpe ko darukọ Bola Tinubu, o ṣe afiwe nipa rẹ ati ẹgbẹ oṣelu APC. O ni ti ilẹ Yoruba ko ba ni ipa kan patọ to fẹ lepa ninu eto idibo naa, ko si idi ti awọn eniyan ni ilẹ Yoruba yoo fi dibo fun ẹgbẹ oselu PDP. ‘’Bawo ni mo se fẹ se ipolongo idibo ni ilẹ Yoruba ki wọn wa dibo fun ẹni ti ẹgbẹ oṣelu gbe?’’ A gbọdọ mọ wipe ẹgbẹ oṣelu alatako PDP mu oludije sipo aarẹ ni ilẹ Yoruba nitori naa awọn ni ohun ti wọn fẹ ta, amọ kini ẹgbẹ oṣelu PDP fẹ ta fun awọn ara ilẹ Niajiria? ‘’Ki awn to wa ni iha Ariwa Niajiria fi ọrọ naa yẹ ara wọn wo, ṣe wọn le faramọ ki oludije sipo aarẹ, igbakeji rẹ ati alaga ẹgbẹ ki wọn wa lati iha Guusu Naijiria, se ara wọn le gba iru rẹ.’’ ‘’Ohun ti mo n sọ ni ki ẹ jẹ ki idajoẹ odoodo ati ṣiṣe didara laarin awọn eniyan jọ wọn loju.’’ ‘’Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Iyorchia Ayu gbọdọ fi ipo silẹ’’ | Ìlera Nnamdi Kanu ń burú si, àìsàn ń ṣe é láti inú - Agbẹjọ́rò Ifeanyi Ejiofor agbẹjọro fun adari ikọ ajijagbara IPOB, Nnamdi Kanu, ti sọrọ sita lori ilera onibara rẹ lẹyin to lugbadi arun miiran. Ejiofor, ninu atẹjade to fi ransẹ sita fawọn akọroyin lọjọ Aje ni onibara oun ni arun to n se eeyan ni inu ati ẹnu, ti oloyinbo pe ni Gastrointestinal Distorder. O ni eyi to mu ki aya ma ta Kanu ni ọpọ igba. O tẹsiwaju pe ileẹjọ giga to wa niluu Abuja labẹ isakoso Adajọ Binta Nyako, palasẹ fun ajọ DSS lati pese ilera to peye fun Nnamdi Kanu sugbọn wọn kọ. O wa ke gbajawire sita lẹyin to ṣe abẹwo si adari IPOB naa ni ọọfisi awọn DSS niluu Abuja lọjọ Ajẹ. “Ni bayi, Nnamdi Kanu n jẹ irora nitori aisan yii, ti o si nilo itọju ni kiakia. “Sugbọn o ṣe ni laanu pe ajọ DSS ko fun ni anfani lati ṣe itọju ara ẹ. “Kete ti a gbọ, ni agbẹjọro agba wa Oloye Mike Ozekhome pasẹ pe ki a bẹrẹ isẹ lati fi ofin si ifiyajẹni naa. Igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ, Olabode George ti fi aidunnu rẹ han si bi ẹgbẹ oṣelu PDP ko ṣe ni nkan gboogi lati fi dije dupo ni ilẹ Yoruba ni idibo ọdun to n bọ. Ninu ọrọ rẹ lori eto tẹlifiṣọn Arise TV lo ti fi ero rẹ han. Bode George ni ẹgbẹ oṣelu PDP ko dabi ẹgbẹ oṣelu APC to jẹ pe iha Guusu Naijiria ni wọn ti mu ẹni ti yoo dije du ipo aarẹ ni Naijiria ni idibo ọdun to n bọ. Bio tilẹ jẹpe ko darukọ Bola Tinubu, o ṣe afiwe nipa rẹ ati ẹgbẹ oṣelu APC. O ni ti ilẹ Yoruba ko ba ni ipa kan patọ to fẹ lepa ninu eto idibo naa, ko si idi ti awọn eniyan ni ilẹ Yoruba yoo fi dibo fun ẹgbẹ oselu PDP. ‘’Bawo ni mo se fẹ se ipolongo idibo ni ilẹ Yoruba ki wọn wa dibo fun ẹni ti ẹgbẹ oṣelu gbe?’’ A gbọdọ mọ wipe ẹgbẹ oṣelu alatako PDP mu oludije sipo aarẹ ni ilẹ Yoruba nitori naa awọn ni ohun ti wọn fẹ ta, amọ kini ẹgbẹ oṣelu PDP fẹ ta fun awọn ara ilẹ Niajiria? ‘’Ki awn to wa ni iha Ariwa Niajiria fi ọrọ naa yẹ ara wọn wo, ṣe wọn le faramọ ki oludije sipo aarẹ, igbakeji rẹ ati alaga ẹgbẹ ki wọn wa lati iha Guusu Naijiria, se ara wọn le gba iru rẹ.’’ ‘’Ohun ti mo n sọ ni ki ẹ jẹ ki idajoẹ odoodo ati ṣiṣe didara laarin awọn eniyan jọ wọn loju.’’ ‘’Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Iyorchia Ayu gbọdọ fi ipo silẹ’’ | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cgrdm04dr3ro |
1entertainment
| Wọ́n ti yọ Portable bíi jìgá kúrò nínú àwọn tí yóò gba àmì ẹ̀yẹ ‘Headies’ nítorí wòtòwótò | Awọn to n ṣagbatẹru ami ẹyẹ Headies, ti yọ orukọ Habeeb Okikiola, ti ọpọ mọ si Portbale kuro lara awọn ti yoo lanfaani lati gba ami ẹyẹ naa lọdun yii. Ninu atẹjade kan loju opo Instagram ni ileeṣẹ Smooth Promotions Limited, to n ṣagbatẹru eto ami ẹyẹ naa ti fi ikede ọhun sita. Atẹjade naa ni “A kabamọ lati kede pe lẹyin awọn ọrọ kobakungbe ti ọgbẹni Okikiola, ti ọpọ mọ si Portable n sọ, eyii to mu ki ilẹeṣẹ ọlọpaa Naijiria atawọn araalu maa sọrọ nipa rẹ, a ti pinnu lati yọ Portable kuro lara awọn ti a fẹ fun ni ami ẹyẹ.” “Igbesẹ wa lati fofin de ọgbẹni Okikiola ko ṣẹyin awọn iwa kobakungbe kan to n wu lori ikanni ibanidọrẹ lori ayelujara.” “Lojọ karundinlọgbọ, oṣu Karun un, o dunkoko pe oun yoo pa, ati pe oun yoo ṣe ijamba fun awọn miran ti a fa kalẹ fun ami ẹyẹ naa ti kii ba ṣe oun lo gba ami ẹyẹ ọhun.” Atẹjade naa tẹsiwaju pe “Lọjọ kejidinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, ọgbẹni Okikiola sọ ninu fidio kan pe oun ni oun da ẹgbẹ okunkun ‘One million boys’to n da ilu ru silẹ.” “Ko tan sibẹ, lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ọgbẹni Habeeb Okikiola tun ya ara rẹ ninu fidio kan, nibi to ti paṣẹ fun awọn ọrẹ rẹ lati lu ọrẹ rẹ mii to fẹsun aṣemaṣe kan, iyẹn DJ Chicken, bii bara.” Lara ami ẹyẹ ti Headies fa Portable kalẹ fun tẹlẹ ni olorin to ta lẹnu julọ larin adugbo ati olorin to ṣẹṣẹ n bọ loke amọ ti irawọ rẹ ti tan. Iwọnba eeyan perete lo mọ Portable tẹlẹ, amọ irawọ rẹ buyọ lẹyin awo orin ‘Zazoo Zehh’ ti oun ati Olamide ati Pocolee gbe jade. | Wọ́n ti yọ Portable bíi jìgá kúrò nínú àwọn tí yóò gba àmì ẹ̀yẹ ‘Headies’ nítorí wòtòwótò Awọn to n ṣagbatẹru ami ẹyẹ Headies, ti yọ orukọ Habeeb Okikiola, ti ọpọ mọ si Portbale kuro lara awọn ti yoo lanfaani lati gba ami ẹyẹ naa lọdun yii. Ninu atẹjade kan loju opo Instagram ni ileeṣẹ Smooth Promotions Limited, to n ṣagbatẹru eto ami ẹyẹ naa ti fi ikede ọhun sita. Atẹjade naa ni “A kabamọ lati kede pe lẹyin awọn ọrọ kobakungbe ti ọgbẹni Okikiola, ti ọpọ mọ si Portable n sọ, eyii to mu ki ilẹeṣẹ ọlọpaa Naijiria atawọn araalu maa sọrọ nipa rẹ, a ti pinnu lati yọ Portable kuro lara awọn ti a fẹ fun ni ami ẹyẹ.” “Igbesẹ wa lati fofin de ọgbẹni Okikiola ko ṣẹyin awọn iwa kobakungbe kan to n wu lori ikanni ibanidọrẹ lori ayelujara.” “Lojọ karundinlọgbọ, oṣu Karun un, o dunkoko pe oun yoo pa, ati pe oun yoo ṣe ijamba fun awọn miran ti a fa kalẹ fun ami ẹyẹ naa ti kii ba ṣe oun lo gba ami ẹyẹ ọhun.” Atẹjade naa tẹsiwaju pe “Lọjọ kejidinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, ọgbẹni Okikiola sọ ninu fidio kan pe oun ni oun da ẹgbẹ okunkun ‘One million boys’to n da ilu ru silẹ.” “Ko tan sibẹ, lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ọgbẹni Habeeb Okikiola tun ya ara rẹ ninu fidio kan, nibi to ti paṣẹ fun awọn ọrẹ rẹ lati lu ọrẹ rẹ mii to fẹsun aṣemaṣe kan, iyẹn DJ Chicken, bii bara.” Lara ami ẹyẹ ti Headies fa Portable kalẹ fun tẹlẹ ni olorin to ta lẹnu julọ larin adugbo ati olorin to ṣẹṣẹ n bọ loke amọ ti irawọ rẹ ti tan. Iwọnba eeyan perete lo mọ Portable tẹlẹ, amọ irawọ rẹ buyọ lẹyin awo orin ‘Zazoo Zehh’ ti oun ati Olamide ati Pocolee gbe jade. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/czr3e9nz1jgo |
3politics
| Wọ́n fẹ́ fi ìgbálẹ̀ àti pankẹ́rẹ́ lé mi kúrò láàfin torí Adeleke, Ọlọrun ló yọ mí – Ataoja Osogbo | Ataoja ti ilu Osogbo, Oba Jimoh Oyetunji, ti ki gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ku oriire. Ọba Oyetunji, ninu fidio kan to lu ori ayelujara pa, lasiko to n ki Adeleke nigba ti gomina tuntun naa ṣabẹwo si aafin rẹ sọ pe, awọn eeyan kan dunkoko mọ oun pe awọn yoo fi pankẹrẹ le oun kuro ninu afin amọ Ọlọrun lo ko oun yọ. Ti ẹ ko ba gbagbe, Adeleke ti kọkọ bẹ aafin Ataoja wo, nibi ti ọba alade naa ti gbe awọn jaduku kan to kọlu awọn alatilẹyin ẹgbẹ PDP ṣepe ninu aafin ọhun. Igbesẹ ti Ataoja gbe naa ko tẹ awọn araalu kan lọrun, eyii to mu ki wọn fẹsun kan ori ade ọhun pe o n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu kan ju awọn miran lọ. Amọ nigba ti Ataoja n sọrọ lasiko ti Adeleke de ba a lalejo lẹyin to jawe olubori ninu idibo gomina tan, o ni kii ṣe Adeleke nikan lo ṣe oriire, nitori oun naa ṣe oriire lẹyin idibo naa. O sọ pe awọn eeyan kan ko ba ti fi pankẹrẹ le oun danu kuro laafin. Ataoja ni “Mo ki gbogbo awa ti Ọlọrun yan gomina tuntun fun pe a ku oriire o, Ọlọrun yoo jẹ ki oriire naa o kalẹ.” “Ẹ jẹ ki wọn mọ pe ayọ mi ti de... ki wọn maa sọ pe awọn yoo fi igbalẹ gba mi bọ sita ninu aafin pẹlu pankẹrẹ.” “Ọlọrun lo yọ mi, kii ṣe Ademola nikan lo ṣoriire, Ataoja Jimoh naa ṣe oriire.” “Ki eku ile o gbọ, ko sọ fun t’oko, kii ṣe emi ni ẹ o fi pankẹrẹ le.” Ataoja pari ọrọ rẹ pe lagbara Ọlọrun, ti Adeleke ba pari saa rẹ tan, yoo ṣe ọdun mẹrin mii si, ti yoo fi pe ọdun mẹjọ lori oye. O wa fikun pe lẹyin naa ni oun yoo tun kede ẹlomiran ti yoo di gomina ipinlẹ Osun. | Wọ́n fẹ́ fi ìgbálẹ̀ àti pankẹ́rẹ́ lé mi kúrò láàfin torí Adeleke, Ọlọrun ló yọ mí – Ataoja Osogbo Ataoja ti ilu Osogbo, Oba Jimoh Oyetunji, ti ki gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ku oriire. Ọba Oyetunji, ninu fidio kan to lu ori ayelujara pa, lasiko to n ki Adeleke nigba ti gomina tuntun naa ṣabẹwo si aafin rẹ sọ pe, awọn eeyan kan dunkoko mọ oun pe awọn yoo fi pankẹrẹ le oun kuro ninu afin amọ Ọlọrun lo ko oun yọ. Ti ẹ ko ba gbagbe, Adeleke ti kọkọ bẹ aafin Ataoja wo, nibi ti ọba alade naa ti gbe awọn jaduku kan to kọlu awọn alatilẹyin ẹgbẹ PDP ṣepe ninu aafin ọhun. Igbesẹ ti Ataoja gbe naa ko tẹ awọn araalu kan lọrun, eyii to mu ki wọn fẹsun kan ori ade ọhun pe o n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu kan ju awọn miran lọ. Amọ nigba ti Ataoja n sọrọ lasiko ti Adeleke de ba a lalejo lẹyin to jawe olubori ninu idibo gomina tan, o ni kii ṣe Adeleke nikan lo ṣe oriire, nitori oun naa ṣe oriire lẹyin idibo naa. O sọ pe awọn eeyan kan ko ba ti fi pankẹrẹ le oun danu kuro laafin. Ataoja ni “Mo ki gbogbo awa ti Ọlọrun yan gomina tuntun fun pe a ku oriire o, Ọlọrun yoo jẹ ki oriire naa o kalẹ.” “Ẹ jẹ ki wọn mọ pe ayọ mi ti de... ki wọn maa sọ pe awọn yoo fi igbalẹ gba mi bọ sita ninu aafin pẹlu pankẹrẹ.” “Ọlọrun lo yọ mi, kii ṣe Ademola nikan lo ṣoriire, Ataoja Jimoh naa ṣe oriire.” “Ki eku ile o gbọ, ko sọ fun t’oko, kii ṣe emi ni ẹ o fi pankẹrẹ le.” Ataoja pari ọrọ rẹ pe lagbara Ọlọrun, ti Adeleke ba pari saa rẹ tan, yoo ṣe ọdun mẹrin mii si, ti yoo fi pe ọdun mẹjọ lori oye. O wa fikun pe lẹyin naa ni oun yoo tun kede ẹlomiran ti yoo di gomina ipinlẹ Osun. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cz9l5mq37r4o |
5sports
| Chichi Igbo: Ọ̀pọ̀ máa ń rò pé mo ní nǹkan ọkùnrin lábẹ́ torí ìrísí mi jọ ti ọkùnrin | Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu lobinrin fun orilẹede Naijiria, Super Falcons, to ti fẹyin ti ni Chichi Igbo jẹ. Ọdun mejidinlogun si lo fi gba bọọlu, ko to fẹyin ti Chichi ni isan, idi ati egungun lile ju awọn ọkunrin miran lọ , ti irisi rẹ ko si yatọ si tawọn ọkunrin amọ obinrin ni. Nigba to n ba BBC sọrọ lori oju ati ohun ti awọn eeyan awujọ n sọ nipa rẹ, Chichi ni ọpọ eeyan lo ti fi ẹnu pa oun lai tii ku. O wa koro oju si awọn ọrọ ibajẹ ti ọpọ eeyan maa n sọ nipa rẹ nitori pe irisi rẹ jọ ti ọkunrin. O si gba awọn eeyan nimọran lati lati ye pa awọn eeyan nipa ọrọ ti wọn ba kọ lawọn oju opo itakun agbaye. | Chichi Igbo: Ọ̀pọ̀ máa ń rò pé mo ní nǹkan ọkùnrin lábẹ́ torí ìrísí mi jọ ti ọkùnrin Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu lobinrin fun orilẹede Naijiria, Super Falcons, to ti fẹyin ti ni Chichi Igbo jẹ. Ọdun mejidinlogun si lo fi gba bọọlu, ko to fẹyin ti Chichi ni isan, idi ati egungun lile ju awọn ọkunrin miran lọ , ti irisi rẹ ko si yatọ si tawọn ọkunrin amọ obinrin ni. Nigba to n ba BBC sọrọ lori oju ati ohun ti awọn eeyan awujọ n sọ nipa rẹ, Chichi ni ọpọ eeyan lo ti fi ẹnu pa oun lai tii ku. O wa koro oju si awọn ọrọ ibajẹ ti ọpọ eeyan maa n sọ nipa rẹ nitori pe irisi rẹ jọ ti ọkunrin. O si gba awọn eeyan nimọran lati lati ye pa awọn eeyan nipa ọrọ ti wọn ba kọ lawọn oju opo itakun agbaye. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-53372798 |
3politics
| 2023: Kò ni sí àyè fún fóònù lílò nínú ojúkòó ìdìbò, ìdí rèé – INEC | Ajọ eleto idibo orilẹede Naijiria (INEC) ti tẹnumọ fifofin de lilo foonu alagbeka nibi ojuko idibo nigba ti gbogbo eniyan ba n kopa ninu eto idibo gbogbogbo ọdun to n bọ. Alaga ajọ eleto idibo naa, Ọjọgbọ Mahmood Yakubu sọ eyi ni ọjọ Aje nibi ipade apero ajọ naa pẹlu awọn tọrọ kan nipa koko ọrọ ti wọn ṣepade le lori, “ipa ti owo n n ni lori idibo.” Wọn n ṣe eyi ṣaaju idibo ọdun 2023. Lara awọn to kopa nibi ipade apero naa ni aṣoju ajọ ọlọpaa, ti ajọ EFCC, ti ajọ ICPC, ajọ to n ri si igbohunsafẹfẹ, awọn ileeṣẹ iroyin, awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba atawọn olugbaninimọran laarin awọn ẹgbẹ oṣelu (IPAC). “Awọn araalu ko gbọdọ gba ki wọn fi owo tan wọn lati ra ibo wọn. Bakan naa, wọn gbudọ kopa gidi ninu fifopin si lilo owo lọna aitọ lasiko idibo nipa ki wọn maa fi ẹjọ iru nnkan bẹẹ sun ajọ INEC tabi awọn ajọ mii to lee kapa rẹ. Lafikun, Awọn adari oṣiṣẹ alaabo gbudọ rii daju pe eyi jẹ koko iṣẹ ayẹwo wọn ṣaaju ati lasiko idibo.” Yakubu sọ bẹẹ. Alaga ajọ INEC fi kun un pe ki awọn to maa n ni anfani lati ba araalu sọrọ ninu gbigbogun ti tita ati rira ibo, awọn bii: Ile ifowopamọ, awọn ile ijọsin, awọn adari ilu nigberiko, awọn oniroyin, ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba ati paapaa julọ, awọn araalu. “Ẹ jẹ ki n lo akoko yii lati fi ran gbogbo araalu leti pe ofin ti a gbe le lilo ẹrọ alagbeka foonu ni ojukoo idibo ṣi wa digbi. Fun igba diẹ bayii, a ti ṣe atunto awọn ibudo idibo wa ki wọn baa le gbe apoti idibo sunmọ ẹgbẹ ojuko idibo lati mu ilana idibo ya ati lati ṣe idiwọ fun awọn karanbani oludibo kan ti yoo fẹ maa fi iwe idibo ti wọn tẹka si han awọn to fẹ ra ibo”. “A n rọ awọn oludibo pe ki wọn ke si awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo nigbakuugba ti wọn ba rii pe awọn eeyan n ru awọn ofin to ṣe koko yii.” O ni oun tun fẹ fi akoko naa fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe awọn ni ipinu lati rii pe ilana ṣiṣe eto idibo ati abajade eto idibo to yanranti lo waye ni Naijria. “A nigbagbọ pe gbogbo ọmọ Naijiria gan fẹ ka ṣe bẹẹ ,” Yakubu sọ eyi. Yakubu wa fi da awọn araalu loju pe INEC yoo tẹsiwaju lati ṣe awọn igbesẹ ti yoo gbogun ti iwa tita ati rira ibo to si fi kun un pe awọn ni ifọkansin fun awọn araalu. O ni INEC ti fẹ ṣe amulo awọn ohun elo imọ ẹrọ igbalode lati rii daju idibo ti ko ni si idiwọ lo waye lọdun 2023. Igbakeji Ọga agba ọlọpaa, Bala Ciroma sọ pe awọn ti fi panpẹ ofin mu ọpọlọpọ awọn to kopa ninu ibo rira to si tun fi kun un ọpọlọpọ tọọgi lawọn ti mu ti wọn n foju wina ofin nile ẹjọ bayii. Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ọlọpaa yoo tun fi iṣẹ kun iṣẹ wọn lati rii daju pe awọn oloṣelu to maa n lọ kaakiri pẹlu ẹru owo nla nla lati fa oju awọn oludibo mọra yoo bọ si gbaga ọlọpaa. Esi yii waye nigba ti aṣoju ẹgbẹ olugbaninimọran laarin awọn oloṣelu mẹnu ba ọrọ “ta ibo koo se’bẹ”. Bakan naa ni ọga agba ajọ to n ri si igbohunsafẹfẹ ka abala ofin wọn to ni ṣe pẹlu idibo fun awọn oniroyin to si ki wọn nilọ lati ma jẹ ki awọn oloṣelu lo wọn. \nO tun ni ki awọn ile iṣẹ igbohunsafẹfẹ rii pe wọn ni akọsilẹ awọn owo iṣẹ ti wọn ba gba lasiko idibo tori ile iṣẹ ti wọn ba gbamu pẹlu iwa to ru ofin alafia ilu ko ni lọ lai jẹ iya. | 2023: Kò ni sí àyè fún fóònù lílò nínú ojúkòó ìdìbò, ìdí rèé – INEC Ajọ eleto idibo orilẹede Naijiria (INEC) ti tẹnumọ fifofin de lilo foonu alagbeka nibi ojuko idibo nigba ti gbogbo eniyan ba n kopa ninu eto idibo gbogbogbo ọdun to n bọ. Alaga ajọ eleto idibo naa, Ọjọgbọ Mahmood Yakubu sọ eyi ni ọjọ Aje nibi ipade apero ajọ naa pẹlu awọn tọrọ kan nipa koko ọrọ ti wọn ṣepade le lori, “ipa ti owo n n ni lori idibo.” Wọn n ṣe eyi ṣaaju idibo ọdun 2023. Lara awọn to kopa nibi ipade apero naa ni aṣoju ajọ ọlọpaa, ti ajọ EFCC, ti ajọ ICPC, ajọ to n ri si igbohunsafẹfẹ, awọn ileeṣẹ iroyin, awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba atawọn olugbaninimọran laarin awọn ẹgbẹ oṣelu (IPAC). “Awọn araalu ko gbọdọ gba ki wọn fi owo tan wọn lati ra ibo wọn. Bakan naa, wọn gbudọ kopa gidi ninu fifopin si lilo owo lọna aitọ lasiko idibo nipa ki wọn maa fi ẹjọ iru nnkan bẹẹ sun ajọ INEC tabi awọn ajọ mii to lee kapa rẹ. Lafikun, Awọn adari oṣiṣẹ alaabo gbudọ rii daju pe eyi jẹ koko iṣẹ ayẹwo wọn ṣaaju ati lasiko idibo.” Yakubu sọ bẹẹ. Alaga ajọ INEC fi kun un pe ki awọn to maa n ni anfani lati ba araalu sọrọ ninu gbigbogun ti tita ati rira ibo, awọn bii: Ile ifowopamọ, awọn ile ijọsin, awọn adari ilu nigberiko, awọn oniroyin, ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba ati paapaa julọ, awọn araalu. “Ẹ jẹ ki n lo akoko yii lati fi ran gbogbo araalu leti pe ofin ti a gbe le lilo ẹrọ alagbeka foonu ni ojukoo idibo ṣi wa digbi. Fun igba diẹ bayii, a ti ṣe atunto awọn ibudo idibo wa ki wọn baa le gbe apoti idibo sunmọ ẹgbẹ ojuko idibo lati mu ilana idibo ya ati lati ṣe idiwọ fun awọn karanbani oludibo kan ti yoo fẹ maa fi iwe idibo ti wọn tẹka si han awọn to fẹ ra ibo”. “A n rọ awọn oludibo pe ki wọn ke si awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo nigbakuugba ti wọn ba rii pe awọn eeyan n ru awọn ofin to ṣe koko yii.” O ni oun tun fẹ fi akoko naa fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe awọn ni ipinu lati rii pe ilana ṣiṣe eto idibo ati abajade eto idibo to yanranti lo waye ni Naijria. “A nigbagbọ pe gbogbo ọmọ Naijiria gan fẹ ka ṣe bẹẹ ,” Yakubu sọ eyi. Yakubu wa fi da awọn araalu loju pe INEC yoo tẹsiwaju lati ṣe awọn igbesẹ ti yoo gbogun ti iwa tita ati rira ibo to si fi kun un pe awọn ni ifọkansin fun awọn araalu. O ni INEC ti fẹ ṣe amulo awọn ohun elo imọ ẹrọ igbalode lati rii daju idibo ti ko ni si idiwọ lo waye lọdun 2023. Igbakeji Ọga agba ọlọpaa, Bala Ciroma sọ pe awọn ti fi panpẹ ofin mu ọpọlọpọ awọn to kopa ninu ibo rira to si tun fi kun un ọpọlọpọ tọọgi lawọn ti mu ti wọn n foju wina ofin nile ẹjọ bayii. Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ọlọpaa yoo tun fi iṣẹ kun iṣẹ wọn lati rii daju pe awọn oloṣelu to maa n lọ kaakiri pẹlu ẹru owo nla nla lati fa oju awọn oludibo mọra yoo bọ si gbaga ọlọpaa. Esi yii waye nigba ti aṣoju ẹgbẹ olugbaninimọran laarin awọn oloṣelu mẹnu ba ọrọ “ta ibo koo se’bẹ”. Bakan naa ni ọga agba ajọ to n ri si igbohunsafẹfẹ ka abala ofin wọn to ni ṣe pẹlu idibo fun awọn oniroyin to si ki wọn nilọ lati ma jẹ ki awọn oloṣelu lo wọn. \nO tun ni ki awọn ile iṣẹ igbohunsafẹfẹ rii pe wọn ni akọsilẹ awọn owo iṣẹ ti wọn ba gba lasiko idibo tori ile iṣẹ ti wọn ba gbamu pẹlu iwa to ru ofin alafia ilu ko ni lọ lai jẹ iya. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cn0j0ljv40ro |
2health
| Coronavirus: Ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìnàjò wá sí Nàíjíríà ló kọjá àbẹ̀wò tó lágbára | Nibayii ti arun Coronavirus ti wọ orilẹede Naijiria, ijọba wa ko sun rara, lati dena itankalẹ arun naa. Amọ ijọba wa ti n gbe igbesẹ lati dena itankalẹ arun naa bayi bẹrẹ lati awọn papakọ ofurufu ilẹ wa. BBC Yoruba ṣe abẹwo si papakọ ofurufu wa, ta si ri itu meje ti awọn osisẹ ibẹ n pa lati ri pe wọn se ayẹwo fun awọn eeyan naa. Ẹ wo fidio yii lati mọ bo se n lọ nibẹ. | Coronavirus: Ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìnàjò wá sí Nàíjíríà ló kọjá àbẹ̀wò tó lágbára Nibayii ti arun Coronavirus ti wọ orilẹede Naijiria, ijọba wa ko sun rara, lati dena itankalẹ arun naa. Amọ ijọba wa ti n gbe igbesẹ lati dena itankalẹ arun naa bayi bẹrẹ lati awọn papakọ ofurufu ilẹ wa. BBC Yoruba ṣe abẹwo si papakọ ofurufu wa, ta si ri itu meje ti awọn osisẹ ibẹ n pa lati ri pe wọn se ayẹwo fun awọn eeyan naa. Ẹ wo fidio yii lati mọ bo se n lọ nibẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51687918 |
4religion
| Bethel Baptist kidnap: Àwọn ajínigbé tú 28 nínú akẹ́kọ̀ọ́ 121 Bethel Baptist tí wọ́n jígbé sílẹ̀ | Mejidinlọgbọn ninu awọn akẹkọọ mọkanlelọgọfa tawọn ajinigbe gbe lọ lati ile ẹkọ Bethel Baptist loṣu to lọ nipinlẹ Kaduna. Pẹlu omije loju lawọn obi awọn akẹkọọ naa fi pade ara wọn lẹyin ti wọn ti lo ogunjọ lakata awọn janduku ajinigbe. Ọkan lara awọn oludasilẹ ile ẹkọ naa, Rev John Joseph Hayab sọ fun BBC pe awọn ajinigbe naa gba lati tu awọn akẹkọọ naa silẹ lẹyin ti wọn jiroro pẹlu obi awọn ọmọ naa. Amọ ko sọ boya awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn jigbe sanwo itusilẹ ki wọn to tu awọn ọmọ naa silẹ. Ṣugbọn Rev Hayab ni o ṣeeṣe ki awọn obi awọn akẹkọọ ti san owo itusilẹ ki wọn to fi wọn silẹ. Rev Hayab sọ pe o ti rẹ awọn ọmọ naa nigba tawọn ajinigbe fi wọn silẹ lalẹ ọjọ Abamẹta. Ni owurọ ọjọ Aiku ni awọn akẹkọọ ọhun lanfaani lati pade awọn obi wọn lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo ara fun wọn tan. Ọjọ karun un oṣu keje ni awọn janduku ajinigbe yabo ile ẹkọ Bethel Baptist nibi ti wọn ti ji awọn akẹkọọ naa gbe lo. Koda awọn ajinigbe ọhun tun yinbọn pa awọn ẹṣọ eleto abo to n ṣọ ilẹ ẹkọ naa. Ijọba ipinlẹ Kaduna ko tii sọ ohun kan lori itusilẹ diẹ lara awọn ọmọ ile ẹkọ Bethel Baptist naa. | Bethel Baptist kidnap: Àwọn ajínigbé tú 28 nínú akẹ́kọ̀ọ́ 121 Bethel Baptist tí wọ́n jígbé sílẹ̀ Mejidinlọgbọn ninu awọn akẹkọọ mọkanlelọgọfa tawọn ajinigbe gbe lọ lati ile ẹkọ Bethel Baptist loṣu to lọ nipinlẹ Kaduna. Pẹlu omije loju lawọn obi awọn akẹkọọ naa fi pade ara wọn lẹyin ti wọn ti lo ogunjọ lakata awọn janduku ajinigbe. Ọkan lara awọn oludasilẹ ile ẹkọ naa, Rev John Joseph Hayab sọ fun BBC pe awọn ajinigbe naa gba lati tu awọn akẹkọọ naa silẹ lẹyin ti wọn jiroro pẹlu obi awọn ọmọ naa. Amọ ko sọ boya awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn jigbe sanwo itusilẹ ki wọn to tu awọn ọmọ naa silẹ. Ṣugbọn Rev Hayab ni o ṣeeṣe ki awọn obi awọn akẹkọọ ti san owo itusilẹ ki wọn to fi wọn silẹ. Rev Hayab sọ pe o ti rẹ awọn ọmọ naa nigba tawọn ajinigbe fi wọn silẹ lalẹ ọjọ Abamẹta. Ni owurọ ọjọ Aiku ni awọn akẹkọọ ọhun lanfaani lati pade awọn obi wọn lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo ara fun wọn tan. Ọjọ karun un oṣu keje ni awọn janduku ajinigbe yabo ile ẹkọ Bethel Baptist nibi ti wọn ti ji awọn akẹkọọ naa gbe lo. Koda awọn ajinigbe ọhun tun yinbọn pa awọn ẹṣọ eleto abo to n ṣọ ilẹ ẹkọ naa. Ijọba ipinlẹ Kaduna ko tii sọ ohun kan lori itusilẹ diẹ lara awọn ọmọ ile ẹkọ Bethel Baptist naa. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57960696 |
4religion
| TB Joshua: Ìjọ COAN ní wòlíì ṣèpàdé lọ́jọ́ Sátidé, kó tó kú lọ́jọ́ náà | Ileesẹ iransẹ TB Joshua ti kede pe oludasilẹ ijọ naa ati agba wolii lorilẹede Naijiria, Temitope Balogun Joshua ti dagbere faye. Gẹgẹ bi ikede kan ti ileesẹ iransẹ naa ati ijọ Church Of ALl Nations fisita loju opo Facebook rẹ, ana ọjọ Satide, ọjọ karun osu Kẹfa ọdun 2021 ni agba wolii naa mi kanlẹ. Wolii Joshua, to dele aye ni ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1963, lo lo ọdun mejidinlọgọta loke eepẹ, ki ọlọjọ to de. Ikede naa fidi rẹ mulẹ pe Ọlọrun kii se ohunkohun lai fi iran rẹ han awọn wolii rẹ saaju, to si tọkasi iwe mimọ Amosi, ori kẹta ẹsẹ keje. Gẹgẹ bi ikede ijọ naa ti wi, Wolii Joshua sọrọ lọjọ Satide lasiko ipade to se pẹlu awọn alabasisẹpọ rẹ fun ileesẹ mohunmaworan ijọ rẹ, Emmanuel TV, to si dabi ẹnipe o n sọ asọtẹlẹ nipa iku rẹ. "Ohun gbogbo ni akoko wa fun, akoko lati wa fun ipade adura wa, akoko lati pade sile lẹyin isin naa si wa pẹlu." Ijọ naa ni o wu Ọlọrun lo mu iransẹ rẹ sọdọ, ifẹ rẹ si ni iku iransẹ rẹ naa jẹ, Wolii si lo akoko igbẹyin rẹ lati sisẹ sin Ọlọrun, ohun ti wọn bi saye fun ree, to gbe ile aye se, to si ku fun. "Wolii fi ogun isisẹ sin ati ifaraẹnijin fun ijọba Ọlọrun silẹ fun iran to n bọ, a si mọ riri adura yin ni akoko yii." Ikede naa ni ọrọ ti wolii TB Joshua sọ kẹyin to fi mi kanlẹ ni pe "ẹ maa sọna, ẹ si maa gbadura." | TB Joshua: Ìjọ COAN ní wòlíì ṣèpàdé lọ́jọ́ Sátidé, kó tó kú lọ́jọ́ náà Ileesẹ iransẹ TB Joshua ti kede pe oludasilẹ ijọ naa ati agba wolii lorilẹede Naijiria, Temitope Balogun Joshua ti dagbere faye. Gẹgẹ bi ikede kan ti ileesẹ iransẹ naa ati ijọ Church Of ALl Nations fisita loju opo Facebook rẹ, ana ọjọ Satide, ọjọ karun osu Kẹfa ọdun 2021 ni agba wolii naa mi kanlẹ. Wolii Joshua, to dele aye ni ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1963, lo lo ọdun mejidinlọgọta loke eepẹ, ki ọlọjọ to de. Ikede naa fidi rẹ mulẹ pe Ọlọrun kii se ohunkohun lai fi iran rẹ han awọn wolii rẹ saaju, to si tọkasi iwe mimọ Amosi, ori kẹta ẹsẹ keje. Gẹgẹ bi ikede ijọ naa ti wi, Wolii Joshua sọrọ lọjọ Satide lasiko ipade to se pẹlu awọn alabasisẹpọ rẹ fun ileesẹ mohunmaworan ijọ rẹ, Emmanuel TV, to si dabi ẹnipe o n sọ asọtẹlẹ nipa iku rẹ. "Ohun gbogbo ni akoko wa fun, akoko lati wa fun ipade adura wa, akoko lati pade sile lẹyin isin naa si wa pẹlu." Ijọ naa ni o wu Ọlọrun lo mu iransẹ rẹ sọdọ, ifẹ rẹ si ni iku iransẹ rẹ naa jẹ, Wolii si lo akoko igbẹyin rẹ lati sisẹ sin Ọlọrun, ohun ti wọn bi saye fun ree, to gbe ile aye se, to si ku fun. "Wolii fi ogun isisẹ sin ati ifaraẹnijin fun ijọba Ọlọrun silẹ fun iran to n bọ, a si mọ riri adura yin ni akoko yii." Ikede naa ni ọrọ ti wolii TB Joshua sọ kẹyin to fi mi kanlẹ ni pe "ẹ maa sọna, ẹ si maa gbadura." | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-57373812 |
3politics
| 2023 Elections: Shehu Sani ní àfàìmọ̀ kí Yorùbá àti Igbo má kùnà nínú ìbò ààrẹ ọdún 2023 | Yoruba ati Ibo le kuna lati jẹ aarẹ orilẹede Naijiria lọdun 2023 ti idibo gbogbgbo miiran yoo tun wa ye. Sẹnẹtọ to wa lara awọn ile igbimọ aṣofin kẹjọ, Shehu Sani lo fọrọ yii lede lọjọ Abamẹta. Sẹnẹtọ tẹlẹ ri sọ pe ti Yoruba ati Igbo ko ba fẹnu ko lori ẹni ti yoo apa guusu orilẹede Naijiria, afai mọ ki ipo aarẹ maa bọ mọ wọn lọwọ lọdun 2023. Shehu Sani lootọ ni ko ni boju mu ki aarẹ Naijiria tun wa lati apa ariwa orilẹede yii ninu idibo ọdun 2023, amọ o le ṣẹlẹ bẹẹ ti awọn eeyan to wa lapa ila oorun ati iwọ oorun guusu ko ba fimọ sọkan. O fikun ọrọ rẹ pe oun gbagbọ ninu pinpin ipo aarẹ lati apa kan si omiran kaakiri Naijiria. Sani aigbọra ẹni ye laarin Yoruba ati Igbo lori oludije ti ṣoju guusu Naijiria ninu ibo aarẹ ọdun 2023 le fun awọn eeyan ariwa lanfaani lati tun jẹ aarẹ lọdun 2023. Aarẹ Muhammadu Buhari to n ṣoju apa ariwa yoo ti lo ọdun ,mẹji lori laeefa to ba pari saa keji rẹ lọdun 2023. | 2023 Elections: Shehu Sani ní àfàìmọ̀ kí Yorùbá àti Igbo má kùnà nínú ìbò ààrẹ ọdún 2023 Yoruba ati Ibo le kuna lati jẹ aarẹ orilẹede Naijiria lọdun 2023 ti idibo gbogbgbo miiran yoo tun wa ye. Sẹnẹtọ to wa lara awọn ile igbimọ aṣofin kẹjọ, Shehu Sani lo fọrọ yii lede lọjọ Abamẹta. Sẹnẹtọ tẹlẹ ri sọ pe ti Yoruba ati Igbo ko ba fẹnu ko lori ẹni ti yoo apa guusu orilẹede Naijiria, afai mọ ki ipo aarẹ maa bọ mọ wọn lọwọ lọdun 2023. Shehu Sani lootọ ni ko ni boju mu ki aarẹ Naijiria tun wa lati apa ariwa orilẹede yii ninu idibo ọdun 2023, amọ o le ṣẹlẹ bẹẹ ti awọn eeyan to wa lapa ila oorun ati iwọ oorun guusu ko ba fimọ sọkan. O fikun ọrọ rẹ pe oun gbagbọ ninu pinpin ipo aarẹ lati apa kan si omiran kaakiri Naijiria. Sani aigbọra ẹni ye laarin Yoruba ati Igbo lori oludije ti ṣoju guusu Naijiria ninu ibo aarẹ ọdun 2023 le fun awọn eeyan ariwa lanfaani lati tun jẹ aarẹ lọdun 2023. Aarẹ Muhammadu Buhari to n ṣoju apa ariwa yoo ti lo ọdun ,mẹji lori laeefa to ba pari saa keji rẹ lọdun 2023. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49462333 |
4religion
| Pásítọ̀ gún ìyàwó rẹ̀ lọ́bẹ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá tì í bọ ara rẹ̀ náà níkùn | Pasitọ ijọ kan ni Kenya ti gun iyawo rẹ lọbẹ pa lọjọ Aiku lori aga iwaasu ninu ṣọọṣi ti awọn mejeji jọ da silẹni ilu kan ni Mombasa, ni orilẹ-ede Kenya. Awọn olujosin to wa nile ijọsin lọjọ naa sọ fun awọn akọroyin pe Pasitọ naa, Elisha Misiko jokoo niwaju ninu ijọ Nibi to joko si nibẹ si lo ti dide lọ ba iyawo rẹ lori pẹpẹ to si gun un pẹlu ọbẹ to fi pamọ sabẹ ẹwu to wọ. Lẹyin eyi lo lo ọbẹ kan naa lati fi gun ikun ara rẹ, bi awọn ọmọ ijọ ṣe tun fẹ sare si wọn lori pẹpẹ lo fi ọbẹ naa ge ara rẹ rẹ ní ọ̀fun. Loju ẹsẹ ni Elisha gbẹmi mi nigba ti iyawo rẹ ku nile iwosan. Ṣaaju ki ọrọ yii to ṣẹlẹ, tọkọ taya yii ti ni aawọ lori tani yoo maa ṣakoso ijọ gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Nation ṣe sọ ọ. Gbogbo bo ṣe ṣẹlẹ yii lawọn ti o ṣoju wọn koro ko iroyin ro fun awọn akọroyin nipa ohun to ti n ṣẹlẹ ninu ile pasitọ yii ati iyawo rẹ. Arabinrin kan ni ṣe ni ọkọ n fi iya jẹ iyawo rẹ to bi ọmọ mẹrin fun un to n ṣe e baṣu baṣu titi ti wọn fi pinya. | Pásítọ̀ gún ìyàwó rẹ̀ lọ́bẹ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá tì í bọ ara rẹ̀ náà níkùn Pasitọ ijọ kan ni Kenya ti gun iyawo rẹ lọbẹ pa lọjọ Aiku lori aga iwaasu ninu ṣọọṣi ti awọn mejeji jọ da silẹni ilu kan ni Mombasa, ni orilẹ-ede Kenya. Awọn olujosin to wa nile ijọsin lọjọ naa sọ fun awọn akọroyin pe Pasitọ naa, Elisha Misiko jokoo niwaju ninu ijọ Nibi to joko si nibẹ si lo ti dide lọ ba iyawo rẹ lori pẹpẹ to si gun un pẹlu ọbẹ to fi pamọ sabẹ ẹwu to wọ. Lẹyin eyi lo lo ọbẹ kan naa lati fi gun ikun ara rẹ, bi awọn ọmọ ijọ ṣe tun fẹ sare si wọn lori pẹpẹ lo fi ọbẹ naa ge ara rẹ rẹ ní ọ̀fun. Loju ẹsẹ ni Elisha gbẹmi mi nigba ti iyawo rẹ ku nile iwosan. Ṣaaju ki ọrọ yii to ṣẹlẹ, tọkọ taya yii ti ni aawọ lori tani yoo maa ṣakoso ijọ gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Nation ṣe sọ ọ. Gbogbo bo ṣe ṣẹlẹ yii lawọn ti o ṣoju wọn koro ko iroyin ro fun awọn akọroyin nipa ohun to ti n ṣẹlẹ ninu ile pasitọ yii ati iyawo rẹ. Arabinrin kan ni ṣe ni ọkọ n fi iya jẹ iyawo rẹ to bi ọmọ mẹrin fun un to n ṣe e baṣu baṣu titi ti wọn fi pinya. | https://www.bbc.com/yoruba/51008121 |
4religion
| Títí tí mo fi pé ẹni ọdún méjìdínlógún, n kò rí bàtà wọ̀ - Adeboye | Oluṣọaguntan agba fun ijọ Redeemed Christian Church of God, Pasitọ Enoch Adeboye ti ṣalaye pe ohun pataki ti ayajọ Keresimesi jẹ fun oun. Adeboye ni oun jẹ ọkan lara awọn eeyan ti iwaye Jesu Kristi, ti ajọdun Keresimesi da le lori, ṣe pataki fun nitori ayipada to mu ba igbe aye oun lati ipo otoṣi wa si ọlọrọ. Pasitọ Adeboye sọrọ yii ninu iwaasu ọdun to gbe kalẹ eyi to pe akori rẹ ni “Ẹbun alailabuku” lọjọ Aiku. Pasitọ Adeboye ni ọdun mejidinlogun gbako ni oun ko fi ri bata wọ si ẹsẹ laye oun. O sọ eyi nigba to n ṣe agbekalẹ ara rẹ gẹgẹ bi apẹrẹ bi Jesu Kristi ṣe n wọ aye eniyan, to si n mu iyipada ba aye bẹẹ. “Gbogbo ẹyin ti ẹ mọ diẹ nipa ipilẹ mi, ẹ o mọ pe atapata dide ẹda ni mi. Inu oṣi to lagbara ni mo ti bẹrẹ. Nibi ti baba mi toṣi de, awọn otoṣi gan an tun n pe e ni otoṣi debi wi pe ni ọjọ to ra aburada, gbogbo wa la n jo. "Fun ọdun mejidinlogun akọkọ nile aye mi, nibi ti nnkan le de, n ko ni bata kankan. Lẹyin eyi mo gba Jesu sinu aye mi, gbogbo nnkan si n yi pada fun mi. Ẹ wo mi loni. Tẹlẹ orukọ ilu mi ko si ninu maapu orilẹede Naijiria. Amọṣa, loni nitori pe mo gba Jesu, orukọ ilu mi ti han ninu iwe afihan maapu gbogbo agbaye.” | Títí tí mo fi pé ẹni ọdún méjìdínlógún, n kò rí bàtà wọ̀ - Adeboye Oluṣọaguntan agba fun ijọ Redeemed Christian Church of God, Pasitọ Enoch Adeboye ti ṣalaye pe ohun pataki ti ayajọ Keresimesi jẹ fun oun. Adeboye ni oun jẹ ọkan lara awọn eeyan ti iwaye Jesu Kristi, ti ajọdun Keresimesi da le lori, ṣe pataki fun nitori ayipada to mu ba igbe aye oun lati ipo otoṣi wa si ọlọrọ. Pasitọ Adeboye sọrọ yii ninu iwaasu ọdun to gbe kalẹ eyi to pe akori rẹ ni “Ẹbun alailabuku” lọjọ Aiku. Pasitọ Adeboye ni ọdun mejidinlogun gbako ni oun ko fi ri bata wọ si ẹsẹ laye oun. O sọ eyi nigba to n ṣe agbekalẹ ara rẹ gẹgẹ bi apẹrẹ bi Jesu Kristi ṣe n wọ aye eniyan, to si n mu iyipada ba aye bẹẹ. “Gbogbo ẹyin ti ẹ mọ diẹ nipa ipilẹ mi, ẹ o mọ pe atapata dide ẹda ni mi. Inu oṣi to lagbara ni mo ti bẹrẹ. Nibi ti baba mi toṣi de, awọn otoṣi gan an tun n pe e ni otoṣi debi wi pe ni ọjọ to ra aburada, gbogbo wa la n jo. "Fun ọdun mejidinlogun akọkọ nile aye mi, nibi ti nnkan le de, n ko ni bata kankan. Lẹyin eyi mo gba Jesu sinu aye mi, gbogbo nnkan si n yi pada fun mi. Ẹ wo mi loni. Tẹlẹ orukọ ilu mi ko si ninu maapu orilẹede Naijiria. Amọṣa, loni nitori pe mo gba Jesu, orukọ ilu mi ti han ninu iwe afihan maapu gbogbo agbaye.” | https://www.bbc.com/yoruba/articles/c6pdmd78jg6o |
3politics
| Ẹ sọ fún Ademọla Adeleke kó yé sáré kìtìkìtì, sáré kàtàkàtà mọ́, kó gbára dúró gba ìwé ìpẹ̀jọ́ mi – Gómìnà Oyetola | Gomina Gboyega Oyetọla ti ipinlẹ Ọṣun ti fi ẹsun kan gomina ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ naa, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu PDP pe o n sa pamọ fun iwe ipẹjọ ti oun fi n tako esi idibo to gbe e wọle gege bii gomina. Gomina Oyetọla ni gbogbo akitiyan lati fun un ni iwe ipẹjọ lati ile ẹjọ naa lo n ja si pabo pẹlu bi Adeleke ṣe n sare kitikiti, sare katakata lati yẹra fun iwe naa. Gomina Oyetọla ni ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye nipa eto idibo gomina ipinlẹ Ọsun ni yoo ba wọn yanju ọrọ naa bayii. Inu oṣu Keje ni gomina ipinlẹ Ọsun ti yoo pari saa rẹ loṣu kọkanla ọdun 2022, Alaaji Gboyega Oyetọla gba ile ẹjọ ti wọn gbe kalẹ fun gbigbọ awuyewuye gbogbo to suyọ nipa idibo gomina nipinlẹ Ọṣun lọ. Ohun ti Oyetọla sọ ninu ipẹjọ rẹ ni pe oun ni ọpọlọpọ idi ati ẹri pe Ademọla Adeleke kọ ni awọn eeyan ilu dibo yan ninu ibo gomina ipinlẹ Ọsun to waye lọjọ kẹrindilogun oṣu Keje. Agbẹjọro Oyetọla, Amofin agba Kunle Adegoke SAN, ṣalaye fun BBC News Yoruba pe lati igba naa ni wọn ti n wa gbogbo ọna lati fun un ni iwe ipẹjọ yii gẹgẹ bi ilana ofin, ṣugbọn ti gomina tilu didbo yan naa ko fẹẹ gba a. “Igbẹjọ ti wọn fẹ gbọ kii ṣe igbẹjọ gangan lori awuyewuye to wa nilẹ ṣugbọn a ni awọn iwe ipenija kan lati le jẹ ki olujẹjọ keji tii ṣe Sẹnetọ Ademọla Adeleke, lati le jẹ ki ile ẹjọ fun wa ni ọna mii lati le jẹ ko gba iwe ipẹjọ nitori pe ko tii gba iwe ipẹjọ lati igba ti a ti gbe ẹjọ wọ ile ẹjọ. O n dibọn. O n yẹra lati ma jẹ ki wọn fun oun. Lati lee baa fi asiko ṣofo.” Amofin agba Kunle Adegoke ni ohun ti awọn fẹ ṣe bayii ni lati rọ ile ẹjọ naa boya ‘a le fun wa laṣẹ lati le jẹ kii, boya ki wọn lọ lẹẹ mọ iwaju ile rẹ ni o tabi ki wọn fun agbalagba kan ti wọn ba ba ni ile rẹ ni o. Lati le jẹ ki ile ẹjọ gba wi pe a ti fun ni iwe naa” Ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye eto ibo gomina l’Ọṣun sọ pe lootọ ni awọn yoo joko lọjọ Aje ṣugbọn kii ṣe lati bẹrẹ igbẹjọ lori awuyewuye eto ibo gomina l’Ọṣun laarin gomina Oyetọla ati Ajọ INEC pẹlu Sẹnetọ Adeleke. Akọwe agba igbimọ igbẹjọ naa David Umar ṣalaye fawọn akọroyin ileeṣẹ iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria pe ohun ti ijoko ọjọ Aje, ọjọ kejilelogun osu kẹjọ ọdun 2022 wa fun ni lati gbọ ipẹjọ ipenija ti igun Oyetọla gbe tọ ile ẹjọ naa wa lori ipenija ti wọn n koju lati fun Sẹnetọ Adeleke ni iwe ipẹjọ. Ohun ti ile ẹjọ naa yoo gbe yẹwo ni boya wọn yoo lo awọn ọna miran lati mu iwe ipẹjọ tọ olujẹjọ naa, iyẹn Sẹnetọ Ademọla Adeleke lara. | Ẹ sọ fún Ademọla Adeleke kó yé sáré kìtìkìtì, sáré kàtàkàtà mọ́, kó gbára dúró gba ìwé ìpẹ̀jọ́ mi – Gómìnà Oyetola Gomina Gboyega Oyetọla ti ipinlẹ Ọṣun ti fi ẹsun kan gomina ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ naa, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu PDP pe o n sa pamọ fun iwe ipẹjọ ti oun fi n tako esi idibo to gbe e wọle gege bii gomina. Gomina Oyetọla ni gbogbo akitiyan lati fun un ni iwe ipẹjọ lati ile ẹjọ naa lo n ja si pabo pẹlu bi Adeleke ṣe n sare kitikiti, sare katakata lati yẹra fun iwe naa. Gomina Oyetọla ni ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye nipa eto idibo gomina ipinlẹ Ọsun ni yoo ba wọn yanju ọrọ naa bayii. Inu oṣu Keje ni gomina ipinlẹ Ọsun ti yoo pari saa rẹ loṣu kọkanla ọdun 2022, Alaaji Gboyega Oyetọla gba ile ẹjọ ti wọn gbe kalẹ fun gbigbọ awuyewuye gbogbo to suyọ nipa idibo gomina nipinlẹ Ọṣun lọ. Ohun ti Oyetọla sọ ninu ipẹjọ rẹ ni pe oun ni ọpọlọpọ idi ati ẹri pe Ademọla Adeleke kọ ni awọn eeyan ilu dibo yan ninu ibo gomina ipinlẹ Ọsun to waye lọjọ kẹrindilogun oṣu Keje. Agbẹjọro Oyetọla, Amofin agba Kunle Adegoke SAN, ṣalaye fun BBC News Yoruba pe lati igba naa ni wọn ti n wa gbogbo ọna lati fun un ni iwe ipẹjọ yii gẹgẹ bi ilana ofin, ṣugbọn ti gomina tilu didbo yan naa ko fẹẹ gba a. “Igbẹjọ ti wọn fẹ gbọ kii ṣe igbẹjọ gangan lori awuyewuye to wa nilẹ ṣugbọn a ni awọn iwe ipenija kan lati le jẹ ki olujẹjọ keji tii ṣe Sẹnetọ Ademọla Adeleke, lati le jẹ ki ile ẹjọ fun wa ni ọna mii lati le jẹ ko gba iwe ipẹjọ nitori pe ko tii gba iwe ipẹjọ lati igba ti a ti gbe ẹjọ wọ ile ẹjọ. O n dibọn. O n yẹra lati ma jẹ ki wọn fun oun. Lati lee baa fi asiko ṣofo.” Amofin agba Kunle Adegoke ni ohun ti awọn fẹ ṣe bayii ni lati rọ ile ẹjọ naa boya ‘a le fun wa laṣẹ lati le jẹ kii, boya ki wọn lọ lẹẹ mọ iwaju ile rẹ ni o tabi ki wọn fun agbalagba kan ti wọn ba ba ni ile rẹ ni o. Lati le jẹ ki ile ẹjọ gba wi pe a ti fun ni iwe naa” Ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye eto ibo gomina l’Ọṣun sọ pe lootọ ni awọn yoo joko lọjọ Aje ṣugbọn kii ṣe lati bẹrẹ igbẹjọ lori awuyewuye eto ibo gomina l’Ọṣun laarin gomina Oyetọla ati Ajọ INEC pẹlu Sẹnetọ Adeleke. Akọwe agba igbimọ igbẹjọ naa David Umar ṣalaye fawọn akọroyin ileeṣẹ iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria pe ohun ti ijoko ọjọ Aje, ọjọ kejilelogun osu kẹjọ ọdun 2022 wa fun ni lati gbọ ipẹjọ ipenija ti igun Oyetọla gbe tọ ile ẹjọ naa wa lori ipenija ti wọn n koju lati fun Sẹnetọ Adeleke ni iwe ipẹjọ. Ohun ti ile ẹjọ naa yoo gbe yẹwo ni boya wọn yoo lo awọn ọna miran lati mu iwe ipẹjọ tọ olujẹjọ naa, iyẹn Sẹnetọ Ademọla Adeleke lara. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/c10v6684y44o |
2health
| Covid-19 Delta variant Update: Ẹ̀dà Delta Variant COVID-19 ń gbèrú síi ní Nàìjíríà, ìjọba àpapọ̀ ra abẹ́rẹ́ àjẹsára 176,000 | Bi ọwọ kẹta ajakalẹ arun COVID-19 tun ti ṣe n gbilẹ sii lorilẹede Naijiria, ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ti sọ pe ẹda kokoro arun naa ti wọn n pe ni Delta variant ti n gbilẹ sii lorilẹede Naijiria bayii ati pe lojumọ eeyan ẹẹdẹgbẹrin lo n ko arun naa. Ni bayii, aadọjọ ẹgbẹrun abẹrẹ ajẹsara Johnson and Johnson ni Naijiria n reti lọjọbọ. Ko din ni ẹgbẹrin o din mẹwaa eeyan to tun ti ko aarun naa laarin wakati mẹrinlelogun sẹyin bi o tilẹ jẹ pe bi awọn eeyan ṣe n ṣe ayẹwo si ko mu ori ya to. Lorilẹede Naijiria, o le ni miliọnu meji eeyan ti o ti ṣe ayẹwo kokoro arun naa, ninu eyi ti nnkan bii ọgọsan ẹgbẹrun eeyan ti ko arun naa to si ran ẹgbẹrun meji ati igba o din marun un eeyan lọ sọrun. Bakan naa lawọn ibudo ayẹwo arun naa kaakiri orilẹede Naijiria wa ni ṣiṣi pẹlu bi awọn dokita ilewosan ẹkọṣẹ iṣegun kaakiri orilẹede Naijiria ṣe n gun le iyanṣẹlodi lọwọlọwọ bayii lori. Amọṣa, ijsba apapọ kede pe awọn ti ra abẹrẹ ajẹsara Johnson and Johnson to to ẹgbẹrun lọna ọgbọn gẹgẹ bi ara igbesẹ lati jawe sobi gbigba abẹrẹ ajẹsara arun ọhun. Bakan naa ni ijsba orilẹede Naijiria tun fi kun un pe oun ṣi n tiraka lati rii pe ọwọ keji abẹrẹ ajẹsara naa tẹ awọn lọwọ lati lee ri pe ọpọ eeyan lo tun n gba abẹrẹ ajẹsara naa bẹrẹ lati sjọ Iṣẹgun ọsẹ to n bọ. Ni bi a ṣe n sọrọ yii, nnkan bii miliọnu mẹrin eeyan lo ti gba abẹrẹ ajọsara COVID-19 pẹlu AstraZenecca ninu igba miliọnu eeyan to wa lorilẹede Naijiria. | Covid-19 Delta variant Update: Ẹ̀dà Delta Variant COVID-19 ń gbèrú síi ní Nàìjíríà, ìjọba àpapọ̀ ra abẹ́rẹ́ àjẹsára 176,000 Bi ọwọ kẹta ajakalẹ arun COVID-19 tun ti ṣe n gbilẹ sii lorilẹede Naijiria, ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ti sọ pe ẹda kokoro arun naa ti wọn n pe ni Delta variant ti n gbilẹ sii lorilẹede Naijiria bayii ati pe lojumọ eeyan ẹẹdẹgbẹrin lo n ko arun naa. Ni bayii, aadọjọ ẹgbẹrun abẹrẹ ajẹsara Johnson and Johnson ni Naijiria n reti lọjọbọ. Ko din ni ẹgbẹrin o din mẹwaa eeyan to tun ti ko aarun naa laarin wakati mẹrinlelogun sẹyin bi o tilẹ jẹ pe bi awọn eeyan ṣe n ṣe ayẹwo si ko mu ori ya to. Lorilẹede Naijiria, o le ni miliọnu meji eeyan ti o ti ṣe ayẹwo kokoro arun naa, ninu eyi ti nnkan bii ọgọsan ẹgbẹrun eeyan ti ko arun naa to si ran ẹgbẹrun meji ati igba o din marun un eeyan lọ sọrun. Bakan naa lawọn ibudo ayẹwo arun naa kaakiri orilẹede Naijiria wa ni ṣiṣi pẹlu bi awọn dokita ilewosan ẹkọṣẹ iṣegun kaakiri orilẹede Naijiria ṣe n gun le iyanṣẹlodi lọwọlọwọ bayii lori. Amọṣa, ijsba apapọ kede pe awọn ti ra abẹrẹ ajẹsara Johnson and Johnson to to ẹgbẹrun lọna ọgbọn gẹgẹ bi ara igbesẹ lati jawe sobi gbigba abẹrẹ ajẹsara arun ọhun. Bakan naa ni ijsba orilẹede Naijiria tun fi kun un pe oun ṣi n tiraka lati rii pe ọwọ keji abẹrẹ ajẹsara naa tẹ awọn lọwọ lati lee ri pe ọpọ eeyan lo tun n gba abẹrẹ ajẹsara naa bẹrẹ lati sjọ Iṣẹgun ọsẹ to n bọ. Ni bi a ṣe n sọrọ yii, nnkan bii miliọnu mẹrin eeyan lo ti gba abẹrẹ ajọsara COVID-19 pẹlu AstraZenecca ninu igba miliọnu eeyan to wa lorilẹede Naijiria. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58191984 |
1entertainment
| Wo àwọn ode eré tí Davido ti pa tì nínú oṣù Kọ́kànlá yìí látàrí ikú Ifeanyi ọmọ rẹ̀ | Gbajugbaja olorin takasufee Naijiria, Davido, ti wọgile ọpọ ode to yẹ ko ti lọ kọrin lẹnu ọsẹ diẹ sẹyin lẹyin iku ọmọ rẹ, Ifeanyi. Lati ibẹrẹ oṣu Kọkanla yii lo ti fi ori ayelujara silẹ, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ ko si ri ni ita gbangba. Koda, lọjọ to pe ẹni ọgbọn ọdun loke eepẹ, ko sọ nnkankan, bẹẹni awọn ololufẹ rẹ ko gbọ ọrọ kankan lati ọdọ rẹ. Lọjọ kọkanlelogun to pe ẹni ọgbọn ọdun naa, ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo ki oriire, ti ọpọ wọn si sọ pe awọn n saaro rẹ. Ṣaaju iku ọmọ rẹ ni Davido ti kọkọ sọ pe oṣu Kọkanla ọdun yii maa yatọ, nitori inu oṣu naa ni yoo pe ẹni ọgbọn ọdun. O sọ pe oun ti ni awọn alakalẹ eto fun inu oṣu naa gẹgẹ bii atẹjade to fi lede loju opo Twitter rẹ. Lara awọn eto ti Davido ti pati ree lẹyin iku ọmọ rẹ; Ilu Atlanta, Georgia lo yẹ ki eto A.W.A.Y yii ti waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla ti a wayii nilẹ Amẹrika. Lara awọn olorin to yẹ ko ṣere nibẹ ni Kizz Daniel, Oxlade, Adekunle Gold, atawọn mii. Ọjọ kan lẹyin ọjọ to yẹ ki eto naa waye ni awọn to n ṣagbatẹru re kede pe awọn ti sun siwaju pẹlu ọdun kan ki Davido le ri aye kẹdun pẹlu awọn ẹbi rẹ. Oṣu Kejila ọdun 2021 ni iroyin gbode pe Davido ti tọwọ bọwe adehun pe ileeṣẹ Puma lati jẹ oju ileeṣe naa. Lati inu oṣu Kẹwaa ọdun yii si ni Davido ti n sọrọ lori ibaṣepọ rẹ ati ileeṣẹ ọhun. Amọ ileeṣẹ naa ti wa kede pe awọn bata tuntun ti wọn fẹ gbe jade ni ibaṣepọ pẹlu Davido ni ko ni waye mọ lasiko yii, awọn si ti ṣetan lati da owo awọn eeyan to ti san owo awọn bata naa ṣaaju pada. Awọn ololufẹ Davido ko gbọ nnkankan lati ọdọ rẹ lọjọ ibi rẹ to pe ọgbọn ọdun laye. Iroyin ni o ti n mura lati ṣe ajọyọ nla fun ọjọ ibi naa ṣaaju iku ọmọ rẹ. Lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lọdun to kọja lo ke si awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn fi owo ṣọwọ si oun lati gbe ọkọ bọgini kan wọ Naijiria, ninu eyii ti awọn araalu ti fi nnkan bii igba miliọnu naira sọwọ si, amọ awọn ọmọ alailobi lo fun ni owo naa ni ikẹyin. Ni bayii to ku ọjọ perete ti wọn yo burawọle fun ẹgbọn Davido, Ademola Adeleke gẹgẹ bii gomina tuntun ni ipinlẹ Osun, ko si ẹni to tii le sọ boya Davido yoo yọju ibi iburawọle naa. Ti ẹ ko ba gbagbe, Davido wa lara awọn mọlẹbi gomina tuntun naa to gbe ipolongo ibo rẹ lori. Davido sọ fun BBC lẹyin eto idibo naa niluu Ede pe oun n ṣatilẹyin fun ẹgbọn oun nitori ẹbi ṣe pataki si oun gidi. | Wo àwọn ode eré tí Davido ti pa tì nínú oṣù Kọ́kànlá yìí látàrí ikú Ifeanyi ọmọ rẹ̀ Gbajugbaja olorin takasufee Naijiria, Davido, ti wọgile ọpọ ode to yẹ ko ti lọ kọrin lẹnu ọsẹ diẹ sẹyin lẹyin iku ọmọ rẹ, Ifeanyi. Lati ibẹrẹ oṣu Kọkanla yii lo ti fi ori ayelujara silẹ, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ ko si ri ni ita gbangba. Koda, lọjọ to pe ẹni ọgbọn ọdun loke eepẹ, ko sọ nnkankan, bẹẹni awọn ololufẹ rẹ ko gbọ ọrọ kankan lati ọdọ rẹ. Lọjọ kọkanlelogun to pe ẹni ọgbọn ọdun naa, ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo ki oriire, ti ọpọ wọn si sọ pe awọn n saaro rẹ. Ṣaaju iku ọmọ rẹ ni Davido ti kọkọ sọ pe oṣu Kọkanla ọdun yii maa yatọ, nitori inu oṣu naa ni yoo pe ẹni ọgbọn ọdun. O sọ pe oun ti ni awọn alakalẹ eto fun inu oṣu naa gẹgẹ bii atẹjade to fi lede loju opo Twitter rẹ. Lara awọn eto ti Davido ti pati ree lẹyin iku ọmọ rẹ; Ilu Atlanta, Georgia lo yẹ ki eto A.W.A.Y yii ti waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla ti a wayii nilẹ Amẹrika. Lara awọn olorin to yẹ ko ṣere nibẹ ni Kizz Daniel, Oxlade, Adekunle Gold, atawọn mii. Ọjọ kan lẹyin ọjọ to yẹ ki eto naa waye ni awọn to n ṣagbatẹru re kede pe awọn ti sun siwaju pẹlu ọdun kan ki Davido le ri aye kẹdun pẹlu awọn ẹbi rẹ. Oṣu Kejila ọdun 2021 ni iroyin gbode pe Davido ti tọwọ bọwe adehun pe ileeṣẹ Puma lati jẹ oju ileeṣe naa. Lati inu oṣu Kẹwaa ọdun yii si ni Davido ti n sọrọ lori ibaṣepọ rẹ ati ileeṣẹ ọhun. Amọ ileeṣẹ naa ti wa kede pe awọn bata tuntun ti wọn fẹ gbe jade ni ibaṣepọ pẹlu Davido ni ko ni waye mọ lasiko yii, awọn si ti ṣetan lati da owo awọn eeyan to ti san owo awọn bata naa ṣaaju pada. Awọn ololufẹ Davido ko gbọ nnkankan lati ọdọ rẹ lọjọ ibi rẹ to pe ọgbọn ọdun laye. Iroyin ni o ti n mura lati ṣe ajọyọ nla fun ọjọ ibi naa ṣaaju iku ọmọ rẹ. Lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lọdun to kọja lo ke si awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn fi owo ṣọwọ si oun lati gbe ọkọ bọgini kan wọ Naijiria, ninu eyii ti awọn araalu ti fi nnkan bii igba miliọnu naira sọwọ si, amọ awọn ọmọ alailobi lo fun ni owo naa ni ikẹyin. Ni bayii to ku ọjọ perete ti wọn yo burawọle fun ẹgbọn Davido, Ademola Adeleke gẹgẹ bii gomina tuntun ni ipinlẹ Osun, ko si ẹni to tii le sọ boya Davido yoo yọju ibi iburawọle naa. Ti ẹ ko ba gbagbe, Davido wa lara awọn mọlẹbi gomina tuntun naa to gbe ipolongo ibo rẹ lori. Davido sọ fun BBC lẹyin eto idibo naa niluu Ede pe oun n ṣatilẹyin fun ẹgbọn oun nitori ẹbi ṣe pataki si oun gidi. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/c87ek4e2r5zo |
5sports
| AFCON 2019: Òde kò dùn fún super Eagles, Madagascar nà wọ́n pẹ̀lú 2-0 | Nkan ko ṣẹnu're fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti Naijiria ni abala akọkọ ati ikeji idije wọn pẹlu akẹẹgbẹ wọn lati orilẹede Madagascar. Ami ayo meji soodo ni Madagascar fi fi ẹyin Super Eagles janlẹ. Igba akọkọ niyi ti ẹgbẹ agbabọọlu Madagascar n kopa ninu idije Afcon. Lori atẹ igbelewọn ajọ to n mojuto bọọlu l'agbaye, ipo kejidinlaadọfa ni Madagascar wa ti Naijiria si wa ni ipo kejilelogoji. Ẹgbẹ agbabọọlu kankan ko ti i bori Madagascar lati igba ti Afcon 2019 ti bẹrẹ. Wọn ti dije lẹẹmẹta. Lọwọlọwọ, ẹgbẹ agbabọọlu Madagascar lo wa ni oke tente atẹ igbelewọn ninu idije Afcon 2019. Idije AFCON to n lọ lọwọ ni orilẹ-ede Egypt ni Naijiria ti koju Madagascar ninu ipele ẹgbẹ ti wọn yoo fi bọ si ti ẹni mẹrindinlogun. Akọnimọọgba Naijiria ni eyi tumọ si pe Ola Aina àti Chidozie Awaziem lo máa di ẹ̀yìn ilé mú nínú ìdíje òní. Rohr ni oun ni idaniloju pe awọn adiẹyin mu mejeeji yii yoo wulo ninu idije ipele ẹlẹni merindinlogun ti o m bọ lọna. O ni oun yọ awọn mejeeji nitori pe wọn fi ara pa ṣaaju idije to kọja. Rohr ṣalaye fawọn oniroyin pe Collins ati Shehu ti n gba itoju to yẹ. Gernot Rohr, akọ́nimọ̀ọ̀gbá Super Eagles ti ni Ola Aina àti Chidozie Awaziem lo máa di ẹ̀yìn ilé mú nínú ìdíje òní. O ni oun mọọmọ yọ wọn ninu idije toni ni ki wọn le sinmi ati pe Naijiria ni awọn agbabọọlu to pé to lati koju Madagascar. Ta ni Madagascar n Naijiria ti gbena woju nirọlẹ yii? Barea to ṣafihan agbara Madagascar ni orukọ inagijẹ ẹgbẹ agbabọọlu Madagascar ti Naijiria n koju loni. Ikọ Agbabọọlu yii ko kopa ri ninu idije ifẹ ẹyẹ agbaye. Igba akọkọ ti wọn n kopa ninu idije AFCON tilẹ Adulawọ ni ti 2019 to n lọ lọwọ ni Egypt. Orilẹ-ede Madagascar ko kopa ninu idije FIFA lati ọdun 1950 si 1970. Lodun 1974 ti wọn fẹ kopa ni wọn tun yọwọ ninu idije. Wọn gbiyanju lọdun 1982, 1994, 1998, 2002, 2006, 2010, 2014, ati 2018 ṣugbọn wọn ko jawe olubori lati le kopa ninu ife ẹyẹ agbaye. Orilẹ-ede Madagascar ko jawe olubori lati kopa ninu idije AFCON ri. Lọdun 2000, 2002, 2004, 2006, 2008, 2010, 2012, 2013, 2015, 2017 ti wọn gbiyanju ẹ ni wọn ko ti bori lati dije rara. Madagascar ninu idije AFCON 2019: Omi ayo meji si meji ni Madagascar ati orilẹ-ede Guinea gbá ni papa iṣere Alexandra ni Egypt to n gbalejo AFCON. Ojo kejilelogun, oṣu kẹfa ni idije naa waye. Bakan naa ni Madagascar ti gbena woju orilẹ-ede Burundi ninu idije to n lọ lọwọ yii. Ni eyi ti wọn ti fun Burundi ni ami ayo ookan si odo lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa. Loni ni wọn yoo koju Super Eagles Naijiria lati mọ ẹni ti agbara wa lọwọ rẹ. Awọn agbabọọlu Madagascar ti ni ki Naijiria ma foju rena awọn nitori pe awọn ko wa ta guguru ninu idije AFCON to n lọ lọwọ ni Egypt. | AFCON 2019: Òde kò dùn fún super Eagles, Madagascar nà wọ́n pẹ̀lú 2-0 Nkan ko ṣẹnu're fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti Naijiria ni abala akọkọ ati ikeji idije wọn pẹlu akẹẹgbẹ wọn lati orilẹede Madagascar. Ami ayo meji soodo ni Madagascar fi fi ẹyin Super Eagles janlẹ. Igba akọkọ niyi ti ẹgbẹ agbabọọlu Madagascar n kopa ninu idije Afcon. Lori atẹ igbelewọn ajọ to n mojuto bọọlu l'agbaye, ipo kejidinlaadọfa ni Madagascar wa ti Naijiria si wa ni ipo kejilelogoji. Ẹgbẹ agbabọọlu kankan ko ti i bori Madagascar lati igba ti Afcon 2019 ti bẹrẹ. Wọn ti dije lẹẹmẹta. Lọwọlọwọ, ẹgbẹ agbabọọlu Madagascar lo wa ni oke tente atẹ igbelewọn ninu idije Afcon 2019. Idije AFCON to n lọ lọwọ ni orilẹ-ede Egypt ni Naijiria ti koju Madagascar ninu ipele ẹgbẹ ti wọn yoo fi bọ si ti ẹni mẹrindinlogun. Akọnimọọgba Naijiria ni eyi tumọ si pe Ola Aina àti Chidozie Awaziem lo máa di ẹ̀yìn ilé mú nínú ìdíje òní. Rohr ni oun ni idaniloju pe awọn adiẹyin mu mejeeji yii yoo wulo ninu idije ipele ẹlẹni merindinlogun ti o m bọ lọna. O ni oun yọ awọn mejeeji nitori pe wọn fi ara pa ṣaaju idije to kọja. Rohr ṣalaye fawọn oniroyin pe Collins ati Shehu ti n gba itoju to yẹ. Gernot Rohr, akọ́nimọ̀ọ̀gbá Super Eagles ti ni Ola Aina àti Chidozie Awaziem lo máa di ẹ̀yìn ilé mú nínú ìdíje òní. O ni oun mọọmọ yọ wọn ninu idije toni ni ki wọn le sinmi ati pe Naijiria ni awọn agbabọọlu to pé to lati koju Madagascar. Ta ni Madagascar n Naijiria ti gbena woju nirọlẹ yii? Barea to ṣafihan agbara Madagascar ni orukọ inagijẹ ẹgbẹ agbabọọlu Madagascar ti Naijiria n koju loni. Ikọ Agbabọọlu yii ko kopa ri ninu idije ifẹ ẹyẹ agbaye. Igba akọkọ ti wọn n kopa ninu idije AFCON tilẹ Adulawọ ni ti 2019 to n lọ lọwọ ni Egypt. Orilẹ-ede Madagascar ko kopa ninu idije FIFA lati ọdun 1950 si 1970. Lodun 1974 ti wọn fẹ kopa ni wọn tun yọwọ ninu idije. Wọn gbiyanju lọdun 1982, 1994, 1998, 2002, 2006, 2010, 2014, ati 2018 ṣugbọn wọn ko jawe olubori lati le kopa ninu ife ẹyẹ agbaye. Orilẹ-ede Madagascar ko jawe olubori lati kopa ninu idije AFCON ri. Lọdun 2000, 2002, 2004, 2006, 2008, 2010, 2012, 2013, 2015, 2017 ti wọn gbiyanju ẹ ni wọn ko ti bori lati dije rara. Madagascar ninu idije AFCON 2019: Omi ayo meji si meji ni Madagascar ati orilẹ-ede Guinea gbá ni papa iṣere Alexandra ni Egypt to n gbalejo AFCON. Ojo kejilelogun, oṣu kẹfa ni idije naa waye. Bakan naa ni Madagascar ti gbena woju orilẹ-ede Burundi ninu idije to n lọ lọwọ yii. Ni eyi ti wọn ti fun Burundi ni ami ayo ookan si odo lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa. Loni ni wọn yoo koju Super Eagles Naijiria lati mọ ẹni ti agbara wa lọwọ rẹ. Awọn agbabọọlu Madagascar ti ni ki Naijiria ma foju rena awọn nitori pe awọn ko wa ta guguru ninu idije AFCON to n lọ lọwọ ni Egypt. | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-48818108 |
4religion
| Àwọn ‘Rev. Sister’ mẹ́rin tí wọ́n jígbé tí gba ìtúsílẹ̀ | Awọn sister mẹrin ti ijọ Jesus the Saviour Generelate, ti ijọ Aguda ni ilu Port Harcourt, ni ipinlẹ Rivers ti gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe to ji wọn gbe ni oju ọna Okigwe-Umulolo ni ijọba ibilẹ Okigwe ni ipinlẹ Imo. Awọn sister mẹrin naa ti orukọ wọn n jẹ Johannes Nwodo, Christabel Echemazu, Liberata Mbamalu ati Benita Agu ni wọn n lọ fun isin idupẹ ti wọn si ra wọn mu. Amọ, Akọwe ile ijọsin naa ti fi iroyin lede pe wọn ti tu wọn silẹ, ti awọn to ji wọn gbe ko si gba nkankan lọwọ wọn. ‘’Pẹlu idunnu ati ayọ ni a fi kede pe awọn sister wa mẹrin ti wọn jigbe ti gba idusilẹ’’ ‘’O jẹ ọjọ manigbagbe fun wa, ti a si fẹ ki gbogbo eniyan ba wa yọ ayọ paapaa awọn to gbadura fun itusilẹ awọn akẹgbẹ wa ninu Oluwa naa.’’ Bakan naa ni wọn dupẹ lọwọ awọn ọmọ lẹyin Kristi to duro ti wọn lasiko ti wọn ji awọn obinrin naa gbe lọ. Awọn agbebọn tun ti ṣekọlu si awọn arinrinajo ni opopona Okigwe si Enugu, ti wọn si ji awọn sister mẹrin gbe lọ. Ninu atẹjade ti Ile ijọsin The Sisters of Jesus the Saviour fi lede ni wọn ti salaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye. Ninu atẹjade ti wọn pe akọle rẹ ni iroyin ibanujẹ ni wọn ti darukọ awọn sister mẹrin ti wọn jigbẹ lọ naa. Ile Ijosin naa ni awọn fi iroyin naa to awọn ọmọlẹyin Kristi leti, ki wọn le fi adura ran won lọwọ ‘’Ni Ọjọ Isinmi ti wọn n lọ fun isin lati ipinlẹ Rivers lọ si Imo fun isin idupẹ ki wọn to ji wọn gbe lọ.’’ ‘’Ẹyin ara ninu Kristi ni a fi ibanujẹ lọpọlọpọ sọ fun yin pe wọn ti ji awọn arabinrin wa mẹrin gbe lọ lasiko ti wn n lọ fun isin ni agbegbe Okigwe si Umulolo ni wọn ti gbe wọn lọ.’’ A fi asiko yii pe fun adura kikan kikan ki wọn tu wọn silẹ lai si ibi. A dura ki Maria, iya wa wa pẹlu wọn ki wọn si fi wọn silẹ laipẹ. Iwadii fihan pe oju popo naa ni ọpọlọpọ iru iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ tẹlẹ ri, to fi mọ Prelate ijọ Methodist Church of Nigeria, Samuel Kanu-Uche ti wọn jigbe ni Oṣu Kẹfa,ọdun 2022. | Àwọn ‘Rev. Sister’ mẹ́rin tí wọ́n jígbé tí gba ìtúsílẹ̀ Awọn sister mẹrin ti ijọ Jesus the Saviour Generelate, ti ijọ Aguda ni ilu Port Harcourt, ni ipinlẹ Rivers ti gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe to ji wọn gbe ni oju ọna Okigwe-Umulolo ni ijọba ibilẹ Okigwe ni ipinlẹ Imo. Awọn sister mẹrin naa ti orukọ wọn n jẹ Johannes Nwodo, Christabel Echemazu, Liberata Mbamalu ati Benita Agu ni wọn n lọ fun isin idupẹ ti wọn si ra wọn mu. Amọ, Akọwe ile ijọsin naa ti fi iroyin lede pe wọn ti tu wọn silẹ, ti awọn to ji wọn gbe ko si gba nkankan lọwọ wọn. ‘’Pẹlu idunnu ati ayọ ni a fi kede pe awọn sister wa mẹrin ti wọn jigbe ti gba idusilẹ’’ ‘’O jẹ ọjọ manigbagbe fun wa, ti a si fẹ ki gbogbo eniyan ba wa yọ ayọ paapaa awọn to gbadura fun itusilẹ awọn akẹgbẹ wa ninu Oluwa naa.’’ Bakan naa ni wọn dupẹ lọwọ awọn ọmọ lẹyin Kristi to duro ti wọn lasiko ti wọn ji awọn obinrin naa gbe lọ. Awọn agbebọn tun ti ṣekọlu si awọn arinrinajo ni opopona Okigwe si Enugu, ti wọn si ji awọn sister mẹrin gbe lọ. Ninu atẹjade ti Ile ijọsin The Sisters of Jesus the Saviour fi lede ni wọn ti salaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye. Ninu atẹjade ti wọn pe akọle rẹ ni iroyin ibanujẹ ni wọn ti darukọ awọn sister mẹrin ti wọn jigbẹ lọ naa. Ile Ijosin naa ni awọn fi iroyin naa to awọn ọmọlẹyin Kristi leti, ki wọn le fi adura ran won lọwọ ‘’Ni Ọjọ Isinmi ti wọn n lọ fun isin lati ipinlẹ Rivers lọ si Imo fun isin idupẹ ki wọn to ji wọn gbe lọ.’’ ‘’Ẹyin ara ninu Kristi ni a fi ibanujẹ lọpọlọpọ sọ fun yin pe wọn ti ji awọn arabinrin wa mẹrin gbe lọ lasiko ti wn n lọ fun isin ni agbegbe Okigwe si Umulolo ni wọn ti gbe wọn lọ.’’ A fi asiko yii pe fun adura kikan kikan ki wọn tu wọn silẹ lai si ibi. A dura ki Maria, iya wa wa pẹlu wọn ki wọn si fi wọn silẹ laipẹ. Iwadii fihan pe oju popo naa ni ọpọlọpọ iru iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ tẹlẹ ri, to fi mọ Prelate ijọ Methodist Church of Nigeria, Samuel Kanu-Uche ti wọn jigbe ni Oṣu Kẹfa,ọdun 2022. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cmm13qzeg5no |
4religion
| Koko iroyin: Àyẹ̀wò di ọ̀ranyàn ni sọọsi, Ẹ̀mí èṣù ni okunfa ipààyàn Benue | Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni. Ìjọ Redeem: Àyẹ̀wò ojú ara wà láti dènà ìjà nínú ìgbeyàwó Ìjọ Ìràpadà ti ẹ̀mi, táa mọ̀ sí The Redeemed Chriatian Church of God (RCCG) ti fi àtẹ̀jáde tuntun kan síta. Atẹjade naa wi pé, láti àkókò yìí lọ, àwọn àfẹ́sọ́nà tó bá fẹ́ se ìgbeyàwó nínú ìjọ náà, ni wọn yóó máa se àyẹ̀wò fúń ṣáájú ìgbeyàwó lórí àwọn ohun to so rọ̀ mọ́ ìbálòpọ̀ àti ìbímọ wọn. Buhari: Ìwà èṣù pátápátá ni ìkọlù àti ìpànìyàn nípínlẹ̀ Benue Aarẹ Muhammadu Buhari ni ẹmi esu lo n gbe inu awọn to n pa eeyan ni ipinlẹ Benue. Aarẹ woye ọrọ yii ninu ọrọ ibanikẹdun to fi ranṣẹ si ibi isinku awọn fada meji atawọn ọmọ ijọ mẹtadinlogun, ti awọn afunrasi apaniyan kan ṣekupa nipinlẹ Benue. Igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo, lo ṣoju fun aarẹ Muhammadu Buhari nibi eto isinku naa.E ka ekunrere re ni bii Ìtakurọ̀sọ máa ń jẹ́ kí ìsọ̀ ìwé ìròyìn dùn | Koko iroyin: Àyẹ̀wò di ọ̀ranyàn ni sọọsi, Ẹ̀mí èṣù ni okunfa ipààyàn Benue Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni. Ìjọ Redeem: Àyẹ̀wò ojú ara wà láti dènà ìjà nínú ìgbeyàwó Ìjọ Ìràpadà ti ẹ̀mi, táa mọ̀ sí The Redeemed Chriatian Church of God (RCCG) ti fi àtẹ̀jáde tuntun kan síta. Atẹjade naa wi pé, láti àkókò yìí lọ, àwọn àfẹ́sọ́nà tó bá fẹ́ se ìgbeyàwó nínú ìjọ náà, ni wọn yóó máa se àyẹ̀wò fúń ṣáájú ìgbeyàwó lórí àwọn ohun to so rọ̀ mọ́ ìbálòpọ̀ àti ìbímọ wọn. Buhari: Ìwà èṣù pátápátá ni ìkọlù àti ìpànìyàn nípínlẹ̀ Benue Aarẹ Muhammadu Buhari ni ẹmi esu lo n gbe inu awọn to n pa eeyan ni ipinlẹ Benue. Aarẹ woye ọrọ yii ninu ọrọ ibanikẹdun to fi ranṣẹ si ibi isinku awọn fada meji atawọn ọmọ ijọ mẹtadinlogun, ti awọn afunrasi apaniyan kan ṣekupa nipinlẹ Benue. Igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo, lo ṣoju fun aarẹ Muhammadu Buhari nibi eto isinku naa.E ka ekunrere re ni bii Ìtakurọ̀sọ máa ń jẹ́ kí ìsọ̀ ìwé ìròyìn dùn | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-44215829 |
1entertainment
| Pasuma daughter: Mo bá ọmọ mi yọ̀ bó ṣé di ọmọ ogun orí omi ilẹ̀ Amẹrika - Wasiu Alabi Pasuma | Gbajugbaja olorin fuji, Wasiu Alabi Pasuma ti ba ọmọ rẹ Opeyemi ṣajọyọ lẹyin ti ọmọ naa darapọ ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi ilẹ Amẹrika. Pasuma sọ pe aṣeyọri ọmọ naa jẹ ohun iwuri fun oun. Nigba to n kede iroyin naa pẹlu aworan ọmọ ọhun loju opo Instagram rẹ, Pasuma ni "ẹ ba mi ṣajọyọ oriire o, ọmọ mi ti di ọkan lara awọn ọmọ ogun ori omi orilẹ-ede Amẹrika." O tẹsiwaju pe "O kare ọmọ mi Opeyemi L'Amẹrika fun iwuri nla ti o jẹ fun emi ati iya rẹ, Ọlọrun yoo maa sin ọ lọ ninu irinajo iṣẹ ti o yan laayo yii." Ti ẹ ko ba gbagbe, obinrin bii mẹta lo bi ọmọ mẹwaa fun Pasuma, ti wọn jẹ obinrin mẹjọ ati ọkunrin meji. Ọmọ ti Pasuma kọkọ bi ni Wasilat Ajibola to kẹkọọ jade ni fasiti Lead City to wa niluu Ibadan, iyẹn ni ipinlẹ Oyo. Lara awọn ọmọ miran ti Pasuma tun bi ni Barakat, Wasbar, Amirah, Opeyemi, Sultan, Waris ati Aliyah. Pasuma jẹ ọkan gboogi lara awọn olorin fuji to milẹ titi julọ ni Naijiria ati kaakiri agbaye. | Pasuma daughter: Mo bá ọmọ mi yọ̀ bó ṣé di ọmọ ogun orí omi ilẹ̀ Amẹrika - Wasiu Alabi Pasuma Gbajugbaja olorin fuji, Wasiu Alabi Pasuma ti ba ọmọ rẹ Opeyemi ṣajọyọ lẹyin ti ọmọ naa darapọ ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi ilẹ Amẹrika. Pasuma sọ pe aṣeyọri ọmọ naa jẹ ohun iwuri fun oun. Nigba to n kede iroyin naa pẹlu aworan ọmọ ọhun loju opo Instagram rẹ, Pasuma ni "ẹ ba mi ṣajọyọ oriire o, ọmọ mi ti di ọkan lara awọn ọmọ ogun ori omi orilẹ-ede Amẹrika." O tẹsiwaju pe "O kare ọmọ mi Opeyemi L'Amẹrika fun iwuri nla ti o jẹ fun emi ati iya rẹ, Ọlọrun yoo maa sin ọ lọ ninu irinajo iṣẹ ti o yan laayo yii." Ti ẹ ko ba gbagbe, obinrin bii mẹta lo bi ọmọ mẹwaa fun Pasuma, ti wọn jẹ obinrin mẹjọ ati ọkunrin meji. Ọmọ ti Pasuma kọkọ bi ni Wasilat Ajibola to kẹkọọ jade ni fasiti Lead City to wa niluu Ibadan, iyẹn ni ipinlẹ Oyo. Lara awọn ọmọ miran ti Pasuma tun bi ni Barakat, Wasbar, Amirah, Opeyemi, Sultan, Waris ati Aliyah. Pasuma jẹ ọkan gboogi lara awọn olorin fuji to milẹ titi julọ ni Naijiria ati kaakiri agbaye. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-55434303 |
1entertainment
| Mistura Asunmo, Iya 2D:1959 ni mo bẹ̀rẹ̀ eré ṣùgbọ́n ń kò ní ọkọ̀ ẹyọ kan di ìsìnyí | Àwa kò ni 'Pension' torí ọjọ́ ikú lọ́jọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ tiata- Iya Ika lomo ejo Àwa kò ni 'Pension' torí ọjọ́ ikú lọ́jọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ tiata- Iya Ika lomo ejo Se ẹ ranti agba ọjẹ osere to kopa pataki ninu ere Ika lọmọ ejo ti Baba Wande ṣe lọpọlọpọ ọdun sẹyin? BBC Yoruba ti wa iya to ṣe iya awọn ọmọge to n ko wọn ranṣẹ si awọn ọkunrin lati lọ fun ejo ni ounjẹ. Mistura Asunmọ ti ọpọ n pe ni iya 2D salaye kikun nipa bo ṣe bẹrẹ ere itage ni ṣiṣe lati ọdun 1959. Kini Iya 2D tun sọ nipa irir re? Mistura ṣalaye ipa ti ere n ko ninu igbe aye osere ati ipenija to n jade lati ara awon to n se ayederu kaseeti ti won n pe ni 'Piracy' O sọ nipa ohun ti oju rẹ ri nipa bi awon eeyna se n tẹwọgba osere ati bi wọn tun ṣe n kọlu osere. O menuba iṣoro aisi owo pa to ninu fiimu ti eeyan ba ṣe. O rọ ijoba lati ba wọn wagbo dẹkun si ọrọ awon to n ji iṣẹ oṣere lo nigboro. | Mistura Asunmo, Iya 2D:1959 ni mo bẹ̀rẹ̀ eré ṣùgbọ́n ń kò ní ọkọ̀ ẹyọ kan di ìsìnyí Àwa kò ni 'Pension' torí ọjọ́ ikú lọ́jọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ tiata- Iya Ika lomo ejo Àwa kò ni 'Pension' torí ọjọ́ ikú lọ́jọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ tiata- Iya Ika lomo ejo Se ẹ ranti agba ọjẹ osere to kopa pataki ninu ere Ika lọmọ ejo ti Baba Wande ṣe lọpọlọpọ ọdun sẹyin? BBC Yoruba ti wa iya to ṣe iya awọn ọmọge to n ko wọn ranṣẹ si awọn ọkunrin lati lọ fun ejo ni ounjẹ. Mistura Asunmọ ti ọpọ n pe ni iya 2D salaye kikun nipa bo ṣe bẹrẹ ere itage ni ṣiṣe lati ọdun 1959. Kini Iya 2D tun sọ nipa irir re? Mistura ṣalaye ipa ti ere n ko ninu igbe aye osere ati ipenija to n jade lati ara awon to n se ayederu kaseeti ti won n pe ni 'Piracy' O sọ nipa ohun ti oju rẹ ri nipa bi awon eeyna se n tẹwọgba osere ati bi wọn tun ṣe n kọlu osere. O menuba iṣoro aisi owo pa to ninu fiimu ti eeyan ba ṣe. O rọ ijoba lati ba wọn wagbo dẹkun si ọrọ awon to n ji iṣẹ oṣere lo nigboro. | https://www.bbc.com/yoruba/62644154 |
1entertainment
| Nollywood: Gbajugbaja òṣèré ''Toromagbe'' nínú fíìmù ''Arelu'' ti jáde láyé | Ẹbi ati ara gbajugbaja oṣere, Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi ti kede iku rẹ ni ẹni mẹtalelọgọta. Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi lo kọpa ninu ere agbelewo ti wọn ṣe ni ọdun 1986, ti wọn si pe akọle rẹ ni ''Arelu''. Ẹgbọn rẹ, Tola Adeniyi lo kede rẹ fun aye pe o ti jade laye. Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi ni o kopa gẹgẹ bi ''Toromagbe'' ninu fiimu naa, to si jẹ ọkọ fun ''ọwọ otori'' ti wọn gbe ninu aginju. | Nollywood: Gbajugbaja òṣèré ''Toromagbe'' nínú fíìmù ''Arelu'' ti jáde láyé Ẹbi ati ara gbajugbaja oṣere, Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi ti kede iku rẹ ni ẹni mẹtalelọgọta. Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi lo kọpa ninu ere agbelewo ti wọn ṣe ni ọdun 1986, ti wọn si pe akọle rẹ ni ''Arelu''. Ẹgbọn rẹ, Tola Adeniyi lo kede rẹ fun aye pe o ti jade laye. Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi ni o kopa gẹgẹ bi ''Toromagbe'' ninu fiimu naa, to si jẹ ọkọ fun ''ọwọ otori'' ti wọn gbe ninu aginju. | https://www.bbc.com/yoruba/55131797 |
3politics
| Zoning of Presidency: Ghali Na’Abba ní Buhari ń dá ìjọba ṣe láì fi lọ ẹnikẹ́ni | Olori ile asoju sofin tẹlẹ, Ghali Umar Na'Abba ti salaye idi ti awọn eeyan ni ariwa Naijiria se n tako pinpin ipo aarẹ si ẹkun kan. Na'Abba ẹni to salaye ọrọ yii lasiko ifọrọwerọ kan lori mohunmaworan Daily Trust ni awọn eeyan ẹkun ariwa lo ri saa isejọba aarẹ Buhari bii fifi anfaani ti ẹkun ariwa ni sofo danu. O ni ọpọ eeyan Ariwa ni ko tako ki ipo aarẹ lọ si ẹkun miran ni asiko yii nitori pe wọn ko ri anfaani kankan lati ara isejọba Buhari. "Kii kuku se pe awọn eeyan ẹkun guusu ati ariwa n kọju ogun si ara wọn amọ ko si bi eeyan yoo ti se ọrẹ to lai ni aawọ nigba mii. Awọn aawọ yii si lo waye nitori awọn idi kan." Olori ile sofin tẹlẹ naa wa se apejuwe aarẹ Buhari bii ẹni to pin ẹkun guusu ati ariwa niya, ti wọn si ro pe o n se ojusaaju fun ẹkun kan. Na'Abba ni se ni aarẹ n da sisẹ funra rẹ, ti ko si fi gba imọran amọ to n dari ilẹ yii ni ilana konko jabele, kaluku lo n se tiẹ. "Ko seese ki eeyan kan maa dari orilẹede kan lọna tawọn eeyan yoo fi ro pe tinu ara rẹ lo n se, eyi ti ko kan araalu. Amọ to ba jẹ pe awọn igbesẹ adanikan gbe yii kan awọn araalu ati eto idẹrun wọn, a jẹ pe o dara nigba naa. Awọn eeyan ẹkun guusu lero pe aarẹ jẹ ẹlẹya mẹya, ti ko si le dari orilẹede yii. Bẹẹ ni eeyan kan tiẹ sọ fun mi pe ọkunrin yii gan ko le dari ile rẹ gan, bawo wa ni yoo se dari orilẹede." Na'Abba ni ko si bi wọn yoo se pin ipo aarẹ si ẹkun kan, ti yoo tẹ gbogbo eeyan lọrun O ni lẹkun ariwa bayii, erongba gbigbe ipo aarẹ lọ si ẹkun miran ko jẹ itẹwọgba fun ọpọ eeyan. Ero ọpọ eeyan ni pe akoko ti aarẹ yii lo lori oye lo jẹ adanu, ti wọn ko si ri anfaani kankan nibẹ. "Ki wa lo de ti awọn eeyan kan yoo se maa sọrọ nipa pinpin ipo aarẹ? Niwọn igba ti wọn ba ti gbagbọ pe awọn ni iye eeyan to yẹ lati dibo yan aarẹ tuntun sipo. Kii ba ẹnikẹni jiroro, niwọn igba to ti daba bẹẹ, o n da sisẹ fun ara rẹ ni. Eeyan ko le jẹ aarẹ tabi wa ni ipokipo nitori pe oun nikan lo gbọn julọ nitori ko si ẹni to gbọ tan." | Zoning of Presidency: Ghali Na’Abba ní Buhari ń dá ìjọba ṣe láì fi lọ ẹnikẹ́ni Olori ile asoju sofin tẹlẹ, Ghali Umar Na'Abba ti salaye idi ti awọn eeyan ni ariwa Naijiria se n tako pinpin ipo aarẹ si ẹkun kan. Na'Abba ẹni to salaye ọrọ yii lasiko ifọrọwerọ kan lori mohunmaworan Daily Trust ni awọn eeyan ẹkun ariwa lo ri saa isejọba aarẹ Buhari bii fifi anfaani ti ẹkun ariwa ni sofo danu. O ni ọpọ eeyan Ariwa ni ko tako ki ipo aarẹ lọ si ẹkun miran ni asiko yii nitori pe wọn ko ri anfaani kankan lati ara isejọba Buhari. "Kii kuku se pe awọn eeyan ẹkun guusu ati ariwa n kọju ogun si ara wọn amọ ko si bi eeyan yoo ti se ọrẹ to lai ni aawọ nigba mii. Awọn aawọ yii si lo waye nitori awọn idi kan." Olori ile sofin tẹlẹ naa wa se apejuwe aarẹ Buhari bii ẹni to pin ẹkun guusu ati ariwa niya, ti wọn si ro pe o n se ojusaaju fun ẹkun kan. Na'Abba ni se ni aarẹ n da sisẹ funra rẹ, ti ko si fi gba imọran amọ to n dari ilẹ yii ni ilana konko jabele, kaluku lo n se tiẹ. "Ko seese ki eeyan kan maa dari orilẹede kan lọna tawọn eeyan yoo fi ro pe tinu ara rẹ lo n se, eyi ti ko kan araalu. Amọ to ba jẹ pe awọn igbesẹ adanikan gbe yii kan awọn araalu ati eto idẹrun wọn, a jẹ pe o dara nigba naa. Awọn eeyan ẹkun guusu lero pe aarẹ jẹ ẹlẹya mẹya, ti ko si le dari orilẹede yii. Bẹẹ ni eeyan kan tiẹ sọ fun mi pe ọkunrin yii gan ko le dari ile rẹ gan, bawo wa ni yoo se dari orilẹede." Na'Abba ni ko si bi wọn yoo se pin ipo aarẹ si ẹkun kan, ti yoo tẹ gbogbo eeyan lọrun O ni lẹkun ariwa bayii, erongba gbigbe ipo aarẹ lọ si ẹkun miran ko jẹ itẹwọgba fun ọpọ eeyan. Ero ọpọ eeyan ni pe akoko ti aarẹ yii lo lori oye lo jẹ adanu, ti wọn ko si ri anfaani kankan nibẹ. "Ki wa lo de ti awọn eeyan kan yoo se maa sọrọ nipa pinpin ipo aarẹ? Niwọn igba ti wọn ba ti gbagbọ pe awọn ni iye eeyan to yẹ lati dibo yan aarẹ tuntun sipo. Kii ba ẹnikẹni jiroro, niwọn igba to ti daba bẹẹ, o n da sisẹ fun ara rẹ ni. Eeyan ko le jẹ aarẹ tabi wa ni ipokipo nitori pe oun nikan lo gbọn julọ nitori ko si ẹni to gbọ tan." | https://www.bbc.com/yoruba/media-59031495 |
1entertainment
| Small Mummy: Ẹ̀bún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ olówó ńlá ni wọn fi sàmì ọjọ́ ìbí ọdún kẹwàá ọmọdé aláwàdà | Yoruba ni ọmọ ti yoo jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu samu samu nitori kekere ni ẹda ti n yan ipa ọna ti yoo tọ nile aye. Bi ọrọ se ri gẹlẹ ree pẹlu ọdọmọde, ọmọ ọdun mẹwa kan to jẹ alawada loju opo ayelujara Instagram, Ashafa Salamot, ti ọpọ eeyan mọ si Small Mummy. Ọdọmọde yii si ni ọpọ eeyan mọ pupọ loju opo Facebook ati Instagram fun awọn ere ati ọrọ agbalagba to maa n fi se awada. Small Mummy, ẹni to bẹrẹ awada lori ayelujara ko to pe ọmọ ọdun meje lo ti pe ọmọ ọdun mẹwaa bayii. Ọpọ ojo ẹbun lo ti wa n rọ si ọdọ ọdọmọde adẹrinposonu naa, eyi ti awọn ololufẹ rẹ n fun. Amọ pabambari ẹbun to tii jọju julọ ti Small Mummy yoo gba fun ajọyọ ọdun kẹwa to de ile aye naa ni ọkọ ayọkẹlẹ olowo iyebiye kan. Awọn ololufẹ rẹ si lo da owow jọ lati ra ọkọ ayọkẹlẹ alawọ funfun naa, tii se alawọ Toyota Sienna, to le gba ero bii meje fun ọdọmọde naa. Ko tan sibẹ o, awọn eeyan naa tun gba nọmba adanikanlo si ara ọkọ naa, eyi ti wọn kọ Small Mummy si lara. Ikede naa ti Small Mummy se soju opo Instagram rẹ lo mu inu ọpọ olulufẹ rẹ dun. Eyi si lo mu Small Mummy di ọdọmọde miran ti yoo gbe ohun ribiribi se lati ipasẹ awada sise ni ori ayelujara. Ọpọ ololufẹ Small Mummy si lo ti n ki adẹrinposonu naa ku oriire nipa ọkọ ayọkẹlẹ naa. Small Mummy nigba to n kede ẹbun ọkọ tuntun naa yin Oluwa logo pe o ka oun ku ara awọn eeyan to n lo mọto lati kekere. O ni "Alihamudullilahi, O seun Jesu, Oluwa o se o. Omije bọ ni oju mi nigba ti mo n kọ ọrọ yii, mo si n dupẹ lọwọ Ọlọrun, ẹni to ti n ba mi se lati ẹyin wa, ti ko si tun ni dawọ duro. Gbogbo awọn eeyan to si da owo jọ lati ra mọto yii fun mi gẹgẹ bii ẹbun ati awọn eeyan ti yoo tun maa da owo jọ lati ra epo sinu rẹ, ko ni se alaini ohun to dara laelae." Small Mummy tun wa ki Manija rẹ to n sisẹ tọsan toru lati ri daju pe isẹ iransẹ ori ayelujara to dawọ le yọri si rere. O ni Ọlọrun yoo san ni ẹsan rere pupọ, to si tun fi ẹmi imoore rẹ han si gbogbo eeyan. Small Mummy wa seleri pe oun yoo tubọ maa mu ki ori awọn ololufẹ oun wu si nipa oun atawọn awada ti yoo maa se. Small Mummy ni alawada ori ayelujara to maa n se bii olori ijọ Ọlọrun lobinrin. Ede Yoruba da lẹnu rẹ, to si maa n sọrọ bii agbalagba. Oun ni ọmọbinrin kan soso laarin ọmọ mẹrin ti awọn obi rẹ bi ati abikẹyin ninu ẹbi naa. Ko si ti pe ọmọ ọdun meje to ti bẹrẹ awada sise ni ori ayelujara, to si ni awọn ẹgbọn oun to jẹ ọkunrin lo fun oun ni iwuri ati imisi awada sise. Small Mummy yii si lo ti gba ami ẹyẹ lorisirisi nidi awada sise lori ayelujara. Bẹẹ ba gbagbe, adẹrinposonu miran lori ayelujara, Emmanuela, toun naa jẹ ọmọ ọdun mẹwa, gbe ohun ribi ribi se. Emmanuela lo kọ ile awodamiẹnu kan fawọn obi rẹ, eyi to kede sori ayelujara. Emmanuella, to bẹrẹ awada sise lori ayelujara lọmọ ọdun marun, ti wa kede loju opo Instagram rẹ pe, oun ti ra ile awodamiẹnu kan fun iya oun. O wa kede pe oun n fi ile mọriri ọpọ atilẹyin, adura ati iwuri ti iya oun n se fun oun ni. | Small Mummy: Ẹ̀bún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ olówó ńlá ni wọn fi sàmì ọjọ́ ìbí ọdún kẹwàá ọmọdé aláwàdà Yoruba ni ọmọ ti yoo jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu samu samu nitori kekere ni ẹda ti n yan ipa ọna ti yoo tọ nile aye. Bi ọrọ se ri gẹlẹ ree pẹlu ọdọmọde, ọmọ ọdun mẹwa kan to jẹ alawada loju opo ayelujara Instagram, Ashafa Salamot, ti ọpọ eeyan mọ si Small Mummy. Ọdọmọde yii si ni ọpọ eeyan mọ pupọ loju opo Facebook ati Instagram fun awọn ere ati ọrọ agbalagba to maa n fi se awada. Small Mummy, ẹni to bẹrẹ awada lori ayelujara ko to pe ọmọ ọdun meje lo ti pe ọmọ ọdun mẹwaa bayii. Ọpọ ojo ẹbun lo ti wa n rọ si ọdọ ọdọmọde adẹrinposonu naa, eyi ti awọn ololufẹ rẹ n fun. Amọ pabambari ẹbun to tii jọju julọ ti Small Mummy yoo gba fun ajọyọ ọdun kẹwa to de ile aye naa ni ọkọ ayọkẹlẹ olowo iyebiye kan. Awọn ololufẹ rẹ si lo da owow jọ lati ra ọkọ ayọkẹlẹ alawọ funfun naa, tii se alawọ Toyota Sienna, to le gba ero bii meje fun ọdọmọde naa. Ko tan sibẹ o, awọn eeyan naa tun gba nọmba adanikanlo si ara ọkọ naa, eyi ti wọn kọ Small Mummy si lara. Ikede naa ti Small Mummy se soju opo Instagram rẹ lo mu inu ọpọ olulufẹ rẹ dun. Eyi si lo mu Small Mummy di ọdọmọde miran ti yoo gbe ohun ribiribi se lati ipasẹ awada sise ni ori ayelujara. Ọpọ ololufẹ Small Mummy si lo ti n ki adẹrinposonu naa ku oriire nipa ọkọ ayọkẹlẹ naa. Small Mummy nigba to n kede ẹbun ọkọ tuntun naa yin Oluwa logo pe o ka oun ku ara awọn eeyan to n lo mọto lati kekere. O ni "Alihamudullilahi, O seun Jesu, Oluwa o se o. Omije bọ ni oju mi nigba ti mo n kọ ọrọ yii, mo si n dupẹ lọwọ Ọlọrun, ẹni to ti n ba mi se lati ẹyin wa, ti ko si tun ni dawọ duro. Gbogbo awọn eeyan to si da owo jọ lati ra mọto yii fun mi gẹgẹ bii ẹbun ati awọn eeyan ti yoo tun maa da owo jọ lati ra epo sinu rẹ, ko ni se alaini ohun to dara laelae." Small Mummy tun wa ki Manija rẹ to n sisẹ tọsan toru lati ri daju pe isẹ iransẹ ori ayelujara to dawọ le yọri si rere. O ni Ọlọrun yoo san ni ẹsan rere pupọ, to si tun fi ẹmi imoore rẹ han si gbogbo eeyan. Small Mummy wa seleri pe oun yoo tubọ maa mu ki ori awọn ololufẹ oun wu si nipa oun atawọn awada ti yoo maa se. Small Mummy ni alawada ori ayelujara to maa n se bii olori ijọ Ọlọrun lobinrin. Ede Yoruba da lẹnu rẹ, to si maa n sọrọ bii agbalagba. Oun ni ọmọbinrin kan soso laarin ọmọ mẹrin ti awọn obi rẹ bi ati abikẹyin ninu ẹbi naa. Ko si ti pe ọmọ ọdun meje to ti bẹrẹ awada sise ni ori ayelujara, to si ni awọn ẹgbọn oun to jẹ ọkunrin lo fun oun ni iwuri ati imisi awada sise. Small Mummy yii si lo ti gba ami ẹyẹ lorisirisi nidi awada sise lori ayelujara. Bẹẹ ba gbagbe, adẹrinposonu miran lori ayelujara, Emmanuela, toun naa jẹ ọmọ ọdun mẹwa, gbe ohun ribi ribi se. Emmanuela lo kọ ile awodamiẹnu kan fawọn obi rẹ, eyi to kede sori ayelujara. Emmanuella, to bẹrẹ awada sise lori ayelujara lọmọ ọdun marun, ti wa kede loju opo Instagram rẹ pe, oun ti ra ile awodamiẹnu kan fun iya oun. O wa kede pe oun n fi ile mọriri ọpọ atilẹyin, adura ati iwuri ti iya oun n se fun oun ni. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60316845 |
2health
| Adewale and Funmilayo Deaf couple taylor: Bí a ṣe tọ́ àwọn mọ wà dàgbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ya ni lẹ́nu | "Àwọn ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta táa bí ń gbọ́ran wọ́n sì le sọ̀rọ̀". Yoruba ni ba o ku, iṣe o tan, eyi lo difa fun lọkọlaya yii ti wọn o jẹ ki ireti wọn o pin botilẹ jẹ pe odi ni awọn mejeeji. Adewale to jẹ ọkọ ṣalaye nipa fifi ọwọ rẹ sọ̀rọ̀ fun BBC Yoruba pe nigba ti wọn bi oun, oun le sọrọ, "ṣugbọn nigba ti mo n dagba ni mo ni ijamba ọkada to fa bi mo ṣe di odi". O ṣalaye pe igba ti wọn maa fi gbe oun de ile iwosan, ti wọ̀n tọju rẹ ti ara rẹ ya tan ni wọn ṣakiyesi pe ko le gbọ ọrọ mọ. Ilu Akure ni Adewale ati OluwaFunmilayo iyawo rẹ ti jọ da owo pọ ti wọn yan jọ yan iṣẹ ranṣọ-ranṣọ laayo. " Mo gbọrọ lati kekere, igba ti mo dagba to ọmọ ọdun mẹsan si mẹwa ni mo ya odi". Adewale ṣalaye pe ile iwe fun awọn odi to wa ni Akure lawọn ti pade. Ọmọ iṣẹ Adewale to n ṣe ongbufọ fun BBC Yoruba, Damilola Faroye ni ọga oun ninu iṣẹ telọ, Adewale lo kọ oun ni ọpọ nkan ti oun mọ nipa fifi ọwọ sọrọ bii odi titi ti oun ti gbayi ni ṣọọṣi oun toun maa n ṣe ongbufọ. Nibayii, Adewale ti n ran aṣọ igbalode "suit" ti awọn alakọwe maa n wọ to fi mọ oniruuru awọn aṣọ igba de igba. Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo Hàà! Yomi wàá ṣẹ̀wọ̀n o! Oò ṣe bí ọlọ́pọlọ rárá, ò kàn ń fi àṣírí Baba Ijesha àti Iyabo Ojo gòkè ni - Femi Branch Bimpe Oyebade tú àṣírí bí Yomi ṣe ń gbógun tìí torí ìbalòpọ̀ Sàdáńkátà! Ẹ̀yin ẹ̀létò ààbò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkọlù sí ilé Sunday Igboho - Ààrẹ Buhari | Adewale and Funmilayo Deaf couple taylor: Bí a ṣe tọ́ àwọn mọ wà dàgbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ya ni lẹ́nu "Àwọn ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta táa bí ń gbọ́ran wọ́n sì le sọ̀rọ̀". Yoruba ni ba o ku, iṣe o tan, eyi lo difa fun lọkọlaya yii ti wọn o jẹ ki ireti wọn o pin botilẹ jẹ pe odi ni awọn mejeeji. Adewale to jẹ ọkọ ṣalaye nipa fifi ọwọ rẹ sọ̀rọ̀ fun BBC Yoruba pe nigba ti wọn bi oun, oun le sọrọ, "ṣugbọn nigba ti mo n dagba ni mo ni ijamba ọkada to fa bi mo ṣe di odi". O ṣalaye pe igba ti wọn maa fi gbe oun de ile iwosan, ti wọ̀n tọju rẹ ti ara rẹ ya tan ni wọn ṣakiyesi pe ko le gbọ ọrọ mọ. Ilu Akure ni Adewale ati OluwaFunmilayo iyawo rẹ ti jọ da owo pọ ti wọn yan jọ yan iṣẹ ranṣọ-ranṣọ laayo. " Mo gbọrọ lati kekere, igba ti mo dagba to ọmọ ọdun mẹsan si mẹwa ni mo ya odi". Adewale ṣalaye pe ile iwe fun awọn odi to wa ni Akure lawọn ti pade. Ọmọ iṣẹ Adewale to n ṣe ongbufọ fun BBC Yoruba, Damilola Faroye ni ọga oun ninu iṣẹ telọ, Adewale lo kọ oun ni ọpọ nkan ti oun mọ nipa fifi ọwọ sọrọ bii odi titi ti oun ti gbayi ni ṣọọṣi oun toun maa n ṣe ongbufọ. Nibayii, Adewale ti n ran aṣọ igbalode "suit" ti awọn alakọwe maa n wọ to fi mọ oniruuru awọn aṣọ igba de igba. Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo Hàà! Yomi wàá ṣẹ̀wọ̀n o! Oò ṣe bí ọlọ́pọlọ rárá, ò kàn ń fi àṣírí Baba Ijesha àti Iyabo Ojo gòkè ni - Femi Branch Bimpe Oyebade tú àṣírí bí Yomi ṣe ń gbógun tìí torí ìbalòpọ̀ Sàdáńkátà! Ẹ̀yin ẹ̀létò ààbò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkọlù sí ilé Sunday Igboho - Ààrẹ Buhari | https://www.bbc.com/yoruba/57759931 |
2health
| Omohtee Twitter: Ìrora púpọ̀ ni mo là kọjá lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tí mo ṣe láti jẹ́ kí ìdí mi tóbi sii - Omotola Taiwo | Omotola Taiwo, ti ọpọ eeyan mọ si "Omohtee" ti ṣalaye ohun toju rẹ ri lẹyin iṣẹ abẹ to ṣe ni ọdọ Dokita Anu, lọna ati jẹ ibadi rẹ tobi sii. Omohtee tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC pe oun kabamọ igbeṣẹ naa, koda, o ni diẹ lo ku ki oun gba ẹmi ara oun. Ẹni ọdun mejidinlọgbọn ọhun to jẹ oniṣowo aṣọ sọ pe, oriṣirṣi eetu lo n jade ni idi oun ati irora ti ko ṣe fẹnusọ lẹyin iṣẹ abẹ naa. Oṣu kinni ọdu 2020 ni Omohtee ṣe iṣẹ abẹ kanti wọn n pe ni 'Liposuction' ti yoo jẹ ki ikun rẹ pẹlẹbẹ, bẹ lo tun fa ọra ikun rẹ, to si jan mọ idi rẹ ki idi ọhun lee tobi si. Omohtee ti fẹsun kan dokita to ṣe iṣẹ abẹ naa, dokia Anu fun iṣẹ ajabanku to ṣe si oun lara. Ṣugbọn dokita Anu ti pee lẹjọ fun ibanilorukọjẹ, to si n bere fun owo itanran miliọnu marundinlọgbọn naira. Nigba to n sọ tẹnu rẹ fun BBC, dokita Anu ni oun kọṣe mọṣẹ, ati pe oun gba iwe ẹri to dantọ. Anu tun sọ pe iṣe Omohtee kọ ni akọja ewe oun, nitori oun ti ṣe awọn iṣe mii to lami laaka to bi ẹgbẹrun kan ṣaaju iṣẹ rẹ. Dokita ọhun pari ọrọ rẹ pe awuyewuye iṣẹ Omohtee ti mu ki oun padanu iye owo to le ni ọgọrun un miliọnu naira, yatọ si pe ijọba ti gbe ile iwosan oun ti. Ijọba Naijiria ti fi ofin gbe dokita kan, Anu Fela (Medcontour), wọn si ti gbe e lọ si ile ẹjọ giga ijọba apapọ ni Ikoyi nilu Eko. Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrin, oṣu Keje, ni ajọ to n daabo bo ẹtọ oníbàràá ni Naijiria, FCCPC, kede pe oun ti mu Anu, to ni ileewosan Medcontour. Iṣẹ abẹ idi ati ọyàn ni Dokita naa ma n ṣe. Awọn onimọ iṣegun maa n pe iru iṣẹ naa ni Cosmetic Surgery. Wọn ni kò fọwọsowọpọ pẹlu wọn lori iwadii ẹsun ti wọn fi kan an pe ọna ti ko tọ ọ lo n gba ṣiṣẹ abẹ. Ọpọlọpọ igba ni awọn eeyan ti pariwo Dokita Anu, ati ileeṣẹ rẹ lori ayelujara lati bi ọdun meji sẹyin. Ẹsun ti wọn fi n kan an ni pe, iṣẹkiṣẹ lo ṣe si ọyàn ati ìdí ti awọn ni ko ba wọn tun ṣe. Wọn ni niṣe ni ìdí tabi ọyàn awọn burẹwa si, tabi ko di ọgbẹ adaajina. Ọkan lara awọn oníbàràá rẹ, lo pariwo sita lori ayelujara l'oṣu Kẹrin pe, iṣẹ abẹ ti Anu ṣe si idi oun ti da aisan si oun lara. Gbogbo igba si ni Dokita Anu ma n sẹ lori awọn ẹsun naa. Lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ni awọn alaṣẹ ti ọfiisi Medcontour pa nilu Eko, lori ẹsun pe oun ṣe iṣẹ ti ko ba ofin mu. Ninu iroyin ti ajọ FCCPC fi sita lọjọ Ẹti, wọn ni awọn fi ofin mu Dokita Anu, nitori pe ko tẹle awọn ilana ti ajọ naa la kalẹ fun iwadii ẹsun naa. Ọga ajọ FCCPC, Babatunde Irukera, ti oun fun'ra rẹ jẹ amofin, ni yoo jẹ olori igbimọ ti yoo rojọ tako. Ojoojumọ ni iye eeyan to n ṣe iṣẹ abẹ ọyan ati idi n pọ si ni Naijiria. | Omohtee Twitter: Ìrora púpọ̀ ni mo là kọjá lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tí mo ṣe láti jẹ́ kí ìdí mi tóbi sii - Omotola Taiwo Omotola Taiwo, ti ọpọ eeyan mọ si "Omohtee" ti ṣalaye ohun toju rẹ ri lẹyin iṣẹ abẹ to ṣe ni ọdọ Dokita Anu, lọna ati jẹ ibadi rẹ tobi sii. Omohtee tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC pe oun kabamọ igbeṣẹ naa, koda, o ni diẹ lo ku ki oun gba ẹmi ara oun. Ẹni ọdun mejidinlọgbọn ọhun to jẹ oniṣowo aṣọ sọ pe, oriṣirṣi eetu lo n jade ni idi oun ati irora ti ko ṣe fẹnusọ lẹyin iṣẹ abẹ naa. Oṣu kinni ọdu 2020 ni Omohtee ṣe iṣẹ abẹ kanti wọn n pe ni 'Liposuction' ti yoo jẹ ki ikun rẹ pẹlẹbẹ, bẹ lo tun fa ọra ikun rẹ, to si jan mọ idi rẹ ki idi ọhun lee tobi si. Omohtee ti fẹsun kan dokita to ṣe iṣẹ abẹ naa, dokia Anu fun iṣẹ ajabanku to ṣe si oun lara. Ṣugbọn dokita Anu ti pee lẹjọ fun ibanilorukọjẹ, to si n bere fun owo itanran miliọnu marundinlọgbọn naira. Nigba to n sọ tẹnu rẹ fun BBC, dokita Anu ni oun kọṣe mọṣẹ, ati pe oun gba iwe ẹri to dantọ. Anu tun sọ pe iṣe Omohtee kọ ni akọja ewe oun, nitori oun ti ṣe awọn iṣe mii to lami laaka to bi ẹgbẹrun kan ṣaaju iṣẹ rẹ. Dokita ọhun pari ọrọ rẹ pe awuyewuye iṣẹ Omohtee ti mu ki oun padanu iye owo to le ni ọgọrun un miliọnu naira, yatọ si pe ijọba ti gbe ile iwosan oun ti. Ijọba Naijiria ti fi ofin gbe dokita kan, Anu Fela (Medcontour), wọn si ti gbe e lọ si ile ẹjọ giga ijọba apapọ ni Ikoyi nilu Eko. Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrin, oṣu Keje, ni ajọ to n daabo bo ẹtọ oníbàràá ni Naijiria, FCCPC, kede pe oun ti mu Anu, to ni ileewosan Medcontour. Iṣẹ abẹ idi ati ọyàn ni Dokita naa ma n ṣe. Awọn onimọ iṣegun maa n pe iru iṣẹ naa ni Cosmetic Surgery. Wọn ni kò fọwọsowọpọ pẹlu wọn lori iwadii ẹsun ti wọn fi kan an pe ọna ti ko tọ ọ lo n gba ṣiṣẹ abẹ. Ọpọlọpọ igba ni awọn eeyan ti pariwo Dokita Anu, ati ileeṣẹ rẹ lori ayelujara lati bi ọdun meji sẹyin. Ẹsun ti wọn fi n kan an ni pe, iṣẹkiṣẹ lo ṣe si ọyàn ati ìdí ti awọn ni ko ba wọn tun ṣe. Wọn ni niṣe ni ìdí tabi ọyàn awọn burẹwa si, tabi ko di ọgbẹ adaajina. Ọkan lara awọn oníbàràá rẹ, lo pariwo sita lori ayelujara l'oṣu Kẹrin pe, iṣẹ abẹ ti Anu ṣe si idi oun ti da aisan si oun lara. Gbogbo igba si ni Dokita Anu ma n sẹ lori awọn ẹsun naa. Lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ni awọn alaṣẹ ti ọfiisi Medcontour pa nilu Eko, lori ẹsun pe oun ṣe iṣẹ ti ko ba ofin mu. Ninu iroyin ti ajọ FCCPC fi sita lọjọ Ẹti, wọn ni awọn fi ofin mu Dokita Anu, nitori pe ko tẹle awọn ilana ti ajọ naa la kalẹ fun iwadii ẹsun naa. Ọga ajọ FCCPC, Babatunde Irukera, ti oun fun'ra rẹ jẹ amofin, ni yoo jẹ olori igbimọ ti yoo rojọ tako. Ojoojumọ ni iye eeyan to n ṣe iṣẹ abẹ ọyan ati idi n pọ si ni Naijiria. | https://www.bbc.com/yoruba/awon-iroyin-miran-53289543 |
4religion
| The First Temptation of Christ: Netflix wọ̀jọ̀gbọ̀n lórí fíìmù tó ní Jesu ní ìbálòdò akọ s'ákọ | Ariwo pe ki awọn eeyan yago fun ileeṣẹ Netflix lo gbode kan bayi loju opo Twitter, lataari sinima kan to ṣapejuwe pe Jesu ni ibalopọ akọ si akọ. Iroyin ni awọn onibara ileeṣẹ ọhun to le ni miliọnu kan lo ti n kọwọ bọwe pe ki ileeṣẹ ọhun dawọ fiimu naa duro. Ti wọn si n fi aidunu wọn han lori sinima agbelewo naa pẹlu ami #BoycottNetflix. Wọn ni sinima ọhun lodi si igbagbọ awọn ọmọ lẹyin Kristi lori igbeaye Jesu. Sinima apanilẹrin ọhun jẹ nipa itan igbesiaye Jesu lẹyin to lo ogoji ọsan ati ogoji oru ni aginju. Gẹgẹ bi sinima naaa ṣe gbee jade, lẹyin naa ni Jesu pada wale pẹlu ọrẹ rẹ okunrin ti orukọ rẹ n jẹ Orlando. Fiimu naa ṣapejuwe pe Jesu ati ọrẹ rẹ Orlando yii n ni ibalopọ okunrin si okunrin, ṣugbọn Jesu sẹ. Lẹyin naa ni Josẹfu, Maria ati Ọlọrun sọ fun Jesu pe oun ni ọmọ Ọlọrun, ti Jesu si dahun pe rara, pe iṣẹ alawada ni oun yan laayo. Lẹyin o rẹyin ni orẹ rẹ Orlando yii fara rẹ han gẹgẹ bii Lucifa to wa dan Jesu wo. | The First Temptation of Christ: Netflix wọ̀jọ̀gbọ̀n lórí fíìmù tó ní Jesu ní ìbálòdò akọ s'ákọ Ariwo pe ki awọn eeyan yago fun ileeṣẹ Netflix lo gbode kan bayi loju opo Twitter, lataari sinima kan to ṣapejuwe pe Jesu ni ibalopọ akọ si akọ. Iroyin ni awọn onibara ileeṣẹ ọhun to le ni miliọnu kan lo ti n kọwọ bọwe pe ki ileeṣẹ ọhun dawọ fiimu naa duro. Ti wọn si n fi aidunu wọn han lori sinima agbelewo naa pẹlu ami #BoycottNetflix. Wọn ni sinima ọhun lodi si igbagbọ awọn ọmọ lẹyin Kristi lori igbeaye Jesu. Sinima apanilẹrin ọhun jẹ nipa itan igbesiaye Jesu lẹyin to lo ogoji ọsan ati ogoji oru ni aginju. Gẹgẹ bi sinima naaa ṣe gbee jade, lẹyin naa ni Jesu pada wale pẹlu ọrẹ rẹ okunrin ti orukọ rẹ n jẹ Orlando. Fiimu naa ṣapejuwe pe Jesu ati ọrẹ rẹ Orlando yii n ni ibalopọ okunrin si okunrin, ṣugbọn Jesu sẹ. Lẹyin naa ni Josẹfu, Maria ati Ọlọrun sọ fun Jesu pe oun ni ọmọ Ọlọrun, ti Jesu si dahun pe rara, pe iṣẹ alawada ni oun yan laayo. Lẹyin o rẹyin ni orẹ rẹ Orlando yii fara rẹ han gẹgẹ bii Lucifa to wa dan Jesu wo. | https://www.bbc.com/yoruba/media-50806425 |
1entertainment
| Bobrisky 2021 Ramadan: Wo ìdí tí Bobrisky kò fi kópa nínú àwẹ̀ Ramadan tó ń lọ lọ́wọ́ | Ko ṣeku ko ṣẹyẹ nipa aṣọ obinrin ati ọkunrin wiwọ, Okuneye Idris Olanrewaju ti ọpọ mọ si Bobrisky ti ṣalaye idi ti ko fi kopa ninu awẹ Ramadan to n lọ lọwọ. Bobrisky sọ loju opo Instagram rẹ pe nkan oṣu oun ni ko foun laye lati gba awẹ awọn musulumi to n lọ lọwọ. ''Awọn eeyan ti n bi mi leere bo ya mo n gba awẹ, ṣugbọn mo n dawọn lohun pe mo n ṣe nkan oṣu mi lọwọ. Gẹgẹ bi ẹsẹ mọ, awẹ awọn obinrin kii pe,'' Bobrisky lo sọ bẹẹ lori ẹrọ Instagram. Ẹwẹ, ero awọn eeyan ṣe ọtọtọtọ lori gudugbẹ ọrọ ti Bobrisky ja lulẹ loju opo Instagram rẹ. Iyalẹnu lọrọ yii jẹ fawọn ololufẹ Bobrisky kan ti wọn ka ọrọ to fi lede loju opo Instagram rẹ. Oloribecca ni tẹ sọ pe ọrọ ti Bobrisky sọ fẹ mu oun daku rangbọndan nigba ti awọn kan bu si ẹrin gbagada. Ogebaby ni tiẹ beere lọwọ Bobrisky pe ṣe nkan oṣu rẹ ko mu inira wa fun un. Annabelle bu si ẹrin gbagada ni tiẹ, o ni Bobrisky ko ni fi ẹrin pa oun niluu Eko. | Bobrisky 2021 Ramadan: Wo ìdí tí Bobrisky kò fi kópa nínú àwẹ̀ Ramadan tó ń lọ lọ́wọ́ Ko ṣeku ko ṣẹyẹ nipa aṣọ obinrin ati ọkunrin wiwọ, Okuneye Idris Olanrewaju ti ọpọ mọ si Bobrisky ti ṣalaye idi ti ko fi kopa ninu awẹ Ramadan to n lọ lọwọ. Bobrisky sọ loju opo Instagram rẹ pe nkan oṣu oun ni ko foun laye lati gba awẹ awọn musulumi to n lọ lọwọ. ''Awọn eeyan ti n bi mi leere bo ya mo n gba awẹ, ṣugbọn mo n dawọn lohun pe mo n ṣe nkan oṣu mi lọwọ. Gẹgẹ bi ẹsẹ mọ, awẹ awọn obinrin kii pe,'' Bobrisky lo sọ bẹẹ lori ẹrọ Instagram. Ẹwẹ, ero awọn eeyan ṣe ọtọtọtọ lori gudugbẹ ọrọ ti Bobrisky ja lulẹ loju opo Instagram rẹ. Iyalẹnu lọrọ yii jẹ fawọn ololufẹ Bobrisky kan ti wọn ka ọrọ to fi lede loju opo Instagram rẹ. Oloribecca ni tẹ sọ pe ọrọ ti Bobrisky sọ fẹ mu oun daku rangbọndan nigba ti awọn kan bu si ẹrin gbagada. Ogebaby ni tiẹ beere lọwọ Bobrisky pe ṣe nkan oṣu rẹ ko mu inira wa fun un. Annabelle bu si ẹrin gbagada ni tiẹ, o ni Bobrisky ko ni fi ẹrin pa oun niluu Eko. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-56838949 |
1entertainment
| Tope Alabi, Adeyinka Alaseyori on Oniduromi: Shola Allyson, Lanre Teriba àtàwọn èèkàn míràn sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Tope Alabi sọ nípa orin 'Oniduro mi' | Afẹfẹ awuyewuye lori ọrọ ti gbajumọ olorin ẹmi, Tọpẹ Alabi sọ nipa orin Oniduro mi ẹ ṣeun ṣi n fẹ kaakiri bayii. Koda, afẹfẹ naa ti fẹ kan awọn olorin ẹmi atawọn gbajumọ awọlumatẹ bayi lorilẹede Naijiria ati loke okun. Shola Allyson lo kọkọ bọ sigboro aye lati sọ ero tirẹ lori ọrọ naa leyi to ni o ku diẹ kaa to. Ninu ọrọ to fi soju opo ayelujara Instagram rẹ, Shola Allyson ni orin ẹmi ti wọn n sọ yii, ti di eyi to ti bukun ọpọlọpọ eeyan kaakiri agbaye, ninu eyi ti oun pẹlu naa ti kọ ẹya orin toun nibẹ. Akọrin "ifẹ bi eji owurọ" naa to ni ẹnu Mama Bọla Arẹ loun ti kọkọ gbọ orin naa nilu Akurẹ lọdun diẹ sẹyin, wa kan sara si Adeyinka Alaṣeyọri to sọ sorin naa di gbajugbaja, O tun kan saara si Alaseyori fun bo ṣe mu orin naa wa si etigbọ ọpọlọpọ eeyan, to si ti mu iyanu ba aye wọn pẹlu. Bakan naa ni akọrin ẹmi miran, Lanre Tẹriba naa ko ṣai da si ọrọ naa. Nibi ayẹyẹ kan ti Yinka Alaṣeyọri atawọn eekan lawujọ miran wa, ni Lanre Tẹriba ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti Tọpẹ Alabi sọ naa to si ni ko si idi fun un lati maa bu ẹnu atẹ lu olorin miran. O ni Tope Alabi gan pẹlu ti fi ọpọlọpọ orukọ miran ṣakawe Ọlọrun, ti ko si si ẹnikẹni to dide takoo. "Sebi awọn kan lo pe Ọlọrun ni o wọ kẹmbẹ re ibi ija, ṣe wọn mọ telọ to ran aṣọ Ọlọrun ni...katikati Catastrophy" Ninu ọrọ tirẹ lori eto kan to ṣe loju opo Instagram rẹ lọjọ Aiku, Adeyinka Alaṣeyọri yẹra fun sisọ ọrọ lori iṣẹlẹ naa, eleyi to tun mu ki ọpọlọpọ awọn ololufẹ rẹ tun kan sara sii. | Tope Alabi, Adeyinka Alaseyori on Oniduromi: Shola Allyson, Lanre Teriba àtàwọn èèkàn míràn sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Tope Alabi sọ nípa orin 'Oniduro mi' Afẹfẹ awuyewuye lori ọrọ ti gbajumọ olorin ẹmi, Tọpẹ Alabi sọ nipa orin Oniduro mi ẹ ṣeun ṣi n fẹ kaakiri bayii. Koda, afẹfẹ naa ti fẹ kan awọn olorin ẹmi atawọn gbajumọ awọlumatẹ bayi lorilẹede Naijiria ati loke okun. Shola Allyson lo kọkọ bọ sigboro aye lati sọ ero tirẹ lori ọrọ naa leyi to ni o ku diẹ kaa to. Ninu ọrọ to fi soju opo ayelujara Instagram rẹ, Shola Allyson ni orin ẹmi ti wọn n sọ yii, ti di eyi to ti bukun ọpọlọpọ eeyan kaakiri agbaye, ninu eyi ti oun pẹlu naa ti kọ ẹya orin toun nibẹ. Akọrin "ifẹ bi eji owurọ" naa to ni ẹnu Mama Bọla Arẹ loun ti kọkọ gbọ orin naa nilu Akurẹ lọdun diẹ sẹyin, wa kan sara si Adeyinka Alaṣeyọri to sọ sorin naa di gbajugbaja, O tun kan saara si Alaseyori fun bo ṣe mu orin naa wa si etigbọ ọpọlọpọ eeyan, to si ti mu iyanu ba aye wọn pẹlu. Bakan naa ni akọrin ẹmi miran, Lanre Tẹriba naa ko ṣai da si ọrọ naa. Nibi ayẹyẹ kan ti Yinka Alaṣeyọri atawọn eekan lawujọ miran wa, ni Lanre Tẹriba ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti Tọpẹ Alabi sọ naa to si ni ko si idi fun un lati maa bu ẹnu atẹ lu olorin miran. O ni Tope Alabi gan pẹlu ti fi ọpọlọpọ orukọ miran ṣakawe Ọlọrun, ti ko si si ẹnikẹni to dide takoo. "Sebi awọn kan lo pe Ọlọrun ni o wọ kẹmbẹ re ibi ija, ṣe wọn mọ telọ to ran aṣọ Ọlọrun ni...katikati Catastrophy" Ninu ọrọ tirẹ lori eto kan to ṣe loju opo Instagram rẹ lọjọ Aiku, Adeyinka Alaṣeyọri yẹra fun sisọ ọrọ lori iṣẹlẹ naa, eleyi to tun mu ki ọpọlọpọ awọn ololufẹ rẹ tun kan sara sii. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57473456 |
2health
| Coronavirus pandemic update: Wo àwọn orílẹ́-èdè tí kò ní coronavirus lágbàáyé | Ajakalẹ arun coronavirus ti ṣọṣẹ kaakiri orilẹ-ede gbogbo lagbaaye a fi orilẹ-ede mẹwaa kan ti ọwọja rẹ ko de. Wọn ṣi ile itura lorilẹ-ede Palau lọdun 1982 ki irin-ajọ igbafẹ to fẹsẹ rinlẹ, ṣugbọn lati igba naa, ọrọ-aje Palau ti gberasọ. Lọdun 2019, ẹgbẹrun lọna aadọrun arinrin-ajo igbafẹ lo ṣabẹwo si Palau, eyi si jẹ ilọpo marun un gbogbo eeyan to wa nilẹ naa. Koda lọdun 2017, ajọ eleto ẹyawo lagbaaye, IMF sọ pe ẹka eto igbafẹ nikan ko ida ogoji ninu iko ọgunrun un ọrọ-aje orilẹ-ede naa. Ṣugbọn ki ajakakẹ aarun covid-19 to de ni gbogbo eleyi. Orilẹ-ede Palau ti ibode rẹ lati oṣu kẹta ọdun 2020. Palau jẹ ọkan lara orilẹede mẹwaa ti ko ni akọsilẹ coronavirus kankan lati igba ti aarun naa ti ba gbogbo aye finra(awọn orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ ajọ iṣọkan agbaye, UNO la n sọ nibi yatọ si North Korea ati Turkmenistan). Lootọọ ni pe ko si ẹni to laarun covid-19 nibẹ, ṣugbọn ajakalẹ aarun coronavirus si ṣakoba fun wọn lọpọlọpọ. Gbajugbaja ile itura Palau ti di titi pa lati oṣu kẹta, koda gbogbo ile ounjẹ naa ṣofo Awọn orilẹede ti ko ni akọsilẹ coronavirus ree Palau Okun to wa ni Palau ko ni afiwe kaakiri agbaye, oludari ile itura Palau, Brian Lee lo sọ bẹẹ. Okun to lawọ rẹsurẹsu lo maa n da Brian lọrun. Gbogbo yara mẹrinlelaadọta to wa nile itura rẹ lawọn alejo maa fẹ n gba tan. Ṣugbọn nnkan ko ṣẹnu 're mọ lati igba ti wọn ti ti ibode pa. Brian ni orilẹede kekere ni Palau, awọn eeyan orilẹede naa kii fẹ gba ile itura Palau. Ogun oṣiṣẹ lo n ṣiṣẹ nilu itura Palau, ko si ẹni ti wọn da duro ninu wọn. Brian ni ''gbogbo awọn oṣiṣẹ lo ṣi n wa sibi iṣẹ bo tilẹ jẹ ko si alejo kankan. O ni ko rọrun lati maa tun ile itura ṣe fun lai si alejo to n gba a. Brian ni ti oun yoo gbiyanju lati ṣe e fun oṣu mẹfa sii lẹyin naa oun le ti ile itura ọhun pa. Ẹwẹ, aarẹ orilẹede naa kede laipẹ yii pe irin-ajo ọkọ ofurufu yoo bẹrẹ pada lọjọ kinni oṣu kẹsan. Marshall Island to wa ni erekusu okun Pacific naa ko ni akọsilẹ aarun covid-19, bo tilẹ jẹ pe coronavirus ṣakoba fun ọrọ-aje ti wọn naa. Awọn arinrin ajo igbafẹ ko lo ṣabẹwo sawọn itura to wa nibẹ lati oṣu kẹta ti wọn ti gbe ibode ti pa. Ẹẹdẹgbẹrin eeyan lo ṣeeṣe ko padanu iṣẹ wọn nitori ajakalẹ aarun covid-19, ọtale lugba o din meji awọn eeyan yii lo n ṣiṣẹ nile itura atawọn ile ounjẹ. Lootọọ ni pe ibode ti wọn ti pe sọ ọpọ di alaini ni Vanautu, ọpọ eeyan ilẹ naa ni ko si fẹ ki wọn ṣi ibode naa pada laipẹ. Dokita Len Tarivonda to jẹ oludari eto ilera nilẹ naa sọ pe ọpọ ọmọ orilẹede naa tawọn eeyan rẹ ko ju ẹgbẹrun un lọna ọdunrun un lọ ko fẹ ki ijọba ṣi ibode pada. Dokita Tarivonda ni ''ohun ti wọn sọ nipe awọn ko fẹ ko aarun nitori awọn ko pọ tẹlẹ lorilẹede naa, bi bẹẹ kọọ, gbogbo eeyan le ku tan patapata. Ọjọ kinni oṣu kẹsan an ọdun 2020 yii ni ijọba orilẹede Vanuata n gbero lati ṣi ibode rẹ pada. Ki lawọn orilẹ-ede ti ko larun covid-19 le ṣe? Ọna abayọ ni kiakia ni pe ki ijọba maa sanwo fawọn oṣiṣẹ atawọn oniṣowo. Ohun miiran ti ijọba tun le ṣe ni ki o ṣeto abẹrẹ ajẹsara fun gbogbo araalu. Oṣiṣẹ ile ifowopamọ Asia, Rommel Rabanal lo sọ bẹẹ, o ni ijọba ni lati ṣeto fun ayẹwo awọn eeyan ki o si ṣeto ibudo iyasọtọ aibaamọ aarun covid-19 le bẹ silẹ. Jonathan Pryke, oludari eto Pacific Island sọ pe oun ko le sọ bo ya kii ṣe titi ibode mawọn alejo lati ilẹ okeere nikan lọna abayọ si ọrọ coronavirus. Amọ, Pryke ṣalaye pe ti wọn ṣi ibode gan an bayii, awọn ọmọ orilẹede Australia ati New Zealand to n maa ṣabẹwo sawọn orilẹede Pacific ko le wa bayii nitori awọn naa ti ti ibode wọn. | Coronavirus pandemic update: Wo àwọn orílẹ́-èdè tí kò ní coronavirus lágbàáyé Ajakalẹ arun coronavirus ti ṣọṣẹ kaakiri orilẹ-ede gbogbo lagbaaye a fi orilẹ-ede mẹwaa kan ti ọwọja rẹ ko de. Wọn ṣi ile itura lorilẹ-ede Palau lọdun 1982 ki irin-ajọ igbafẹ to fẹsẹ rinlẹ, ṣugbọn lati igba naa, ọrọ-aje Palau ti gberasọ. Lọdun 2019, ẹgbẹrun lọna aadọrun arinrin-ajo igbafẹ lo ṣabẹwo si Palau, eyi si jẹ ilọpo marun un gbogbo eeyan to wa nilẹ naa. Koda lọdun 2017, ajọ eleto ẹyawo lagbaaye, IMF sọ pe ẹka eto igbafẹ nikan ko ida ogoji ninu iko ọgunrun un ọrọ-aje orilẹ-ede naa. Ṣugbọn ki ajakakẹ aarun covid-19 to de ni gbogbo eleyi. Orilẹ-ede Palau ti ibode rẹ lati oṣu kẹta ọdun 2020. Palau jẹ ọkan lara orilẹede mẹwaa ti ko ni akọsilẹ coronavirus kankan lati igba ti aarun naa ti ba gbogbo aye finra(awọn orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ ajọ iṣọkan agbaye, UNO la n sọ nibi yatọ si North Korea ati Turkmenistan). Lootọọ ni pe ko si ẹni to laarun covid-19 nibẹ, ṣugbọn ajakalẹ aarun coronavirus si ṣakoba fun wọn lọpọlọpọ. Gbajugbaja ile itura Palau ti di titi pa lati oṣu kẹta, koda gbogbo ile ounjẹ naa ṣofo Awọn orilẹede ti ko ni akọsilẹ coronavirus ree Palau Okun to wa ni Palau ko ni afiwe kaakiri agbaye, oludari ile itura Palau, Brian Lee lo sọ bẹẹ. Okun to lawọ rẹsurẹsu lo maa n da Brian lọrun. Gbogbo yara mẹrinlelaadọta to wa nile itura rẹ lawọn alejo maa fẹ n gba tan. Ṣugbọn nnkan ko ṣẹnu 're mọ lati igba ti wọn ti ti ibode pa. Brian ni orilẹede kekere ni Palau, awọn eeyan orilẹede naa kii fẹ gba ile itura Palau. Ogun oṣiṣẹ lo n ṣiṣẹ nilu itura Palau, ko si ẹni ti wọn da duro ninu wọn. Brian ni ''gbogbo awọn oṣiṣẹ lo ṣi n wa sibi iṣẹ bo tilẹ jẹ ko si alejo kankan. O ni ko rọrun lati maa tun ile itura ṣe fun lai si alejo to n gba a. Brian ni ti oun yoo gbiyanju lati ṣe e fun oṣu mẹfa sii lẹyin naa oun le ti ile itura ọhun pa. Ẹwẹ, aarẹ orilẹede naa kede laipẹ yii pe irin-ajo ọkọ ofurufu yoo bẹrẹ pada lọjọ kinni oṣu kẹsan. Marshall Island to wa ni erekusu okun Pacific naa ko ni akọsilẹ aarun covid-19, bo tilẹ jẹ pe coronavirus ṣakoba fun ọrọ-aje ti wọn naa. Awọn arinrin ajo igbafẹ ko lo ṣabẹwo sawọn itura to wa nibẹ lati oṣu kẹta ti wọn ti gbe ibode ti pa. Ẹẹdẹgbẹrin eeyan lo ṣeeṣe ko padanu iṣẹ wọn nitori ajakalẹ aarun covid-19, ọtale lugba o din meji awọn eeyan yii lo n ṣiṣẹ nile itura atawọn ile ounjẹ. Lootọọ ni pe ibode ti wọn ti pe sọ ọpọ di alaini ni Vanautu, ọpọ eeyan ilẹ naa ni ko si fẹ ki wọn ṣi ibode naa pada laipẹ. Dokita Len Tarivonda to jẹ oludari eto ilera nilẹ naa sọ pe ọpọ ọmọ orilẹede naa tawọn eeyan rẹ ko ju ẹgbẹrun un lọna ọdunrun un lọ ko fẹ ki ijọba ṣi ibode pada. Dokita Tarivonda ni ''ohun ti wọn sọ nipe awọn ko fẹ ko aarun nitori awọn ko pọ tẹlẹ lorilẹede naa, bi bẹẹ kọọ, gbogbo eeyan le ku tan patapata. Ọjọ kinni oṣu kẹsan an ọdun 2020 yii ni ijọba orilẹede Vanuata n gbero lati ṣi ibode rẹ pada. Ki lawọn orilẹ-ede ti ko larun covid-19 le ṣe? Ọna abayọ ni kiakia ni pe ki ijọba maa sanwo fawọn oṣiṣẹ atawọn oniṣowo. Ohun miiran ti ijọba tun le ṣe ni ki o ṣeto abẹrẹ ajẹsara fun gbogbo araalu. Oṣiṣẹ ile ifowopamọ Asia, Rommel Rabanal lo sọ bẹẹ, o ni ijọba ni lati ṣeto fun ayẹwo awọn eeyan ki o si ṣeto ibudo iyasọtọ aibaamọ aarun covid-19 le bẹ silẹ. Jonathan Pryke, oludari eto Pacific Island sọ pe oun ko le sọ bo ya kii ṣe titi ibode mawọn alejo lati ilẹ okeere nikan lọna abayọ si ọrọ coronavirus. Amọ, Pryke ṣalaye pe ti wọn ṣi ibode gan an bayii, awọn ọmọ orilẹede Australia ati New Zealand to n maa ṣabẹwo sawọn orilẹede Pacific ko le wa bayii nitori awọn naa ti ti ibode wọn. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-53971196 |
5sports
| Maduka Okoye: Wo ohun tí o lè má mọ̀ nípa Maduka Okoye, aṣọ́lé Nàìjíríà tó ń dá àwọn obìnrin lọ́rùn | Orukọ aṣọle Super Eagles Naijiria, Maduka Okoye lo wa lẹnu ọpọ obinrin Naijiria bayii. Ibeere ti eeyan le beere ni pe, ṣe nitori idije ere bọọlu AFCON 2021 ti Naijiria n kopa lọwọ ninu rẹ ni Cameroon ni Okoye fi n dawọn lọrun? Iyalẹnu lo jẹ nitori ẹwa ti Eledua fi jinki Maduka ọmọ Okoye lawọn obninrin fi n sọ nipa rẹ papaa julọ lori itakun agbọrọkaye Twitter. Okoye ti inagijẹ rẹ n jẹ ''Madu'' ti di ilumọọka lati igba ti idije AFCON ti bẹrẹ ni Cameroon. Okoye gba bọọlu fun ikọ Super Eagles Naijiria fun igba akọkọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ti Naijiria ti koju Brazil lọdun 2019. Ẹgbẹ agbabọọlu Fortuna Dusseldorf ni Germany lo n gba bọọlu fun nigba naa. Okoye ṣoju ikọ agbabọọlu ọdọ Bayer Leverkusen ati Fortuna Düsseldorf ti o to darapọ mọ Sparta Rotterdam loṣu keje ọdun 2020. Wọnyii ni awọn koko kan ti o le ma mọ nipa Maduka Okoye: 1. Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 1999 ni wọn bi Maduka Okoye ni Dusseldorf lorilẹede Germany. Ọmọ Naijiria ni baba rẹ, amọ ọmọbibi orilẹede Germany iya to bi i lọmọ. 2. Okoye fi Naijria silẹ lọ si Germany lọmọ ọdun mẹfa, ko si pada wale fun ọdun mẹrinla. 3. Ọmọ Enugu ni baba rẹ, Okoye gbe niluu Enugu, Abuja ati ilu Eko fun igba diẹ ki o to morile Germany nibi to ti dagba to si ti di agbabọọlu. 4. Wọn pe Okoye si ikọ agbabọọlu U23 Naijiria lọdun 2019, ṣugbọn ko le wa nitori ikọ to n gbabọọlu fun ko fi i silẹ. 5. Ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keje ọdun 2019, akọnimọọgba Super Eagles tẹlẹ ri, Gernot Rohr ni oun fẹ pe Maduka lati wa darapọ mọ Super Eagles lẹyin ti aisan Carl Ikeme bẹrẹ. | Maduka Okoye: Wo ohun tí o lè má mọ̀ nípa Maduka Okoye, aṣọ́lé Nàìjíríà tó ń dá àwọn obìnrin lọ́rùn Orukọ aṣọle Super Eagles Naijiria, Maduka Okoye lo wa lẹnu ọpọ obinrin Naijiria bayii. Ibeere ti eeyan le beere ni pe, ṣe nitori idije ere bọọlu AFCON 2021 ti Naijiria n kopa lọwọ ninu rẹ ni Cameroon ni Okoye fi n dawọn lọrun? Iyalẹnu lo jẹ nitori ẹwa ti Eledua fi jinki Maduka ọmọ Okoye lawọn obninrin fi n sọ nipa rẹ papaa julọ lori itakun agbọrọkaye Twitter. Okoye ti inagijẹ rẹ n jẹ ''Madu'' ti di ilumọọka lati igba ti idije AFCON ti bẹrẹ ni Cameroon. Okoye gba bọọlu fun ikọ Super Eagles Naijiria fun igba akọkọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ti Naijiria ti koju Brazil lọdun 2019. Ẹgbẹ agbabọọlu Fortuna Dusseldorf ni Germany lo n gba bọọlu fun nigba naa. Okoye ṣoju ikọ agbabọọlu ọdọ Bayer Leverkusen ati Fortuna Düsseldorf ti o to darapọ mọ Sparta Rotterdam loṣu keje ọdun 2020. Wọnyii ni awọn koko kan ti o le ma mọ nipa Maduka Okoye: 1. Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 1999 ni wọn bi Maduka Okoye ni Dusseldorf lorilẹede Germany. Ọmọ Naijiria ni baba rẹ, amọ ọmọbibi orilẹede Germany iya to bi i lọmọ. 2. Okoye fi Naijria silẹ lọ si Germany lọmọ ọdun mẹfa, ko si pada wale fun ọdun mẹrinla. 3. Ọmọ Enugu ni baba rẹ, Okoye gbe niluu Enugu, Abuja ati ilu Eko fun igba diẹ ki o to morile Germany nibi to ti dagba to si ti di agbabọọlu. 4. Wọn pe Okoye si ikọ agbabọọlu U23 Naijiria lọdun 2019, ṣugbọn ko le wa nitori ikọ to n gbabọọlu fun ko fi i silẹ. 5. Ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keje ọdun 2019, akọnimọọgba Super Eagles tẹlẹ ri, Gernot Rohr ni oun fẹ pe Maduka lati wa darapọ mọ Super Eagles lẹyin ti aisan Carl Ikeme bẹrẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60096975 |
2health
| 2nd wave of Covid-19: Wo bí àjọyọ̀ ọdún ṣe lè wáyé ní ìpínlẹ̀ rẹ̀ lọ́dún yìí lábẹ́ àwọn òfin tuntun nípa COVID-19 | Wo bi ajọyọ ọdun ṣe lee waye ni ipinlẹ rẹ labẹ awọn ofin COVID-19 tuntun Opin ọdun de, pọpọṣinṣin ọdun tẹlee, bẹẹni ipenija ati ipaya nipa ọwọ keji ajakalẹ aarun COVID-19 naa ko gbẹyin; gbogbo rẹ lopin ọdun 2020 yii naa ni. Ni iru asiko yii, kaakiri agbaye lawọn eeyan yoo ti maa minijọjọ kiri ti wọn yoo si maa gbaradi fun oniruuru ipejọpọ pọpọṣinsin ọdun eleyii ti ko ni ri bẹẹ lọdun 2020 bayii nitori awọn akọtun iṣẹlẹ ajakalẹ aarun COVID-19 lagbye bayii, ti ko si yọ Naijiria silẹ. Idi niyi ti awọn ijsba lẹkajẹka, ipinlẹ ati ti apapọ pẹlu ṣe ti gbe awọn aṣẹ kan silẹ fun titẹle lasiko ọdun yii ki ajakalẹ arun naa ma baa di tọrọ fọkale lorilẹede Naijiria. Eyi ni awọn igbesẹ tawọn to wa ni ijanu iṣejọba lawọn ipinlẹ to wa lẹkun iwọ ooru gusu orilẹede Naijiria gbe lati dena ọwọja aarun COVID-1 Ipinlẹ Ondo wa lara awọn ipinlẹ to kọkọ gbe igbesẹ lori ilana bi awọn olugbe ipinlẹ naa yoo ṣe ṣe ọdun si. Iwọgile awọn ayẹyẹ Keresimesi ati opin ọdin gbogbo bii adura aisun ọdun, ayẹyẹ ọlọpọ ero Carnival, pẹlu ayẹyẹ wẹjẹwẹmu gbogbo. Lẹyin ti gomina ipinlẹ naa ti lugbadi aarun COVID ti iroyin si tun ti n fihan pe iye awọn to n ko aarun naa lojoojumọ tunt ti n peleke sii gẹgẹ bi awọn agbejade ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun lorilẹede Naijiria, NCDC ṣe n gbe e jade lojojumọ ni Gomina Babajide Sanwo-Olu ti gbe awọn ilana akọtun sita ti yoo de bi ọrs pọpọṣin'sin ọdun yoo ṣe lọ ni ipinlẹ naa. Lara awọn ilana to gbe kalẹ ree. Laipẹ yii ni awọn oluwadi ijinlẹ nipa kokoro arun ni ibudo iwadi imọ igbalode nipa kokoro arun to wa lọgba fasiti Redeemers University ni ilu Ẹdẹ pariwo sita pe o jọ bi ẹni pe ẹya tuntun kokoro aarun COVID-19 ti wọ ipinlẹ Ọṣun eleyi to ko jinijini bo ọpọ. Ijọba ipinlẹ naa gbe awọn ilana kan kalẹ lati rii daju pe wahala ajakalẹ arun naa ko tun burẹkẹ lẹẹkeji. Ipinlẹ Ekiti naa ko gbẹyin ninu igbesẹ ilana lati wa ọwọ ajakalẹ arun COVID-19 to tun fẹ maa gbẹnu soke bayii bọlẹ. | 2nd wave of Covid-19: Wo bí àjọyọ̀ ọdún ṣe lè wáyé ní ìpínlẹ̀ rẹ̀ lọ́dún yìí lábẹ́ àwọn òfin tuntun nípa COVID-19 Wo bi ajọyọ ọdun ṣe lee waye ni ipinlẹ rẹ labẹ awọn ofin COVID-19 tuntun Opin ọdun de, pọpọṣinṣin ọdun tẹlee, bẹẹni ipenija ati ipaya nipa ọwọ keji ajakalẹ aarun COVID-19 naa ko gbẹyin; gbogbo rẹ lopin ọdun 2020 yii naa ni. Ni iru asiko yii, kaakiri agbaye lawọn eeyan yoo ti maa minijọjọ kiri ti wọn yoo si maa gbaradi fun oniruuru ipejọpọ pọpọṣinsin ọdun eleyii ti ko ni ri bẹẹ lọdun 2020 bayii nitori awọn akọtun iṣẹlẹ ajakalẹ aarun COVID-19 lagbye bayii, ti ko si yọ Naijiria silẹ. Idi niyi ti awọn ijsba lẹkajẹka, ipinlẹ ati ti apapọ pẹlu ṣe ti gbe awọn aṣẹ kan silẹ fun titẹle lasiko ọdun yii ki ajakalẹ arun naa ma baa di tọrọ fọkale lorilẹede Naijiria. Eyi ni awọn igbesẹ tawọn to wa ni ijanu iṣejọba lawọn ipinlẹ to wa lẹkun iwọ ooru gusu orilẹede Naijiria gbe lati dena ọwọja aarun COVID-1 Ipinlẹ Ondo wa lara awọn ipinlẹ to kọkọ gbe igbesẹ lori ilana bi awọn olugbe ipinlẹ naa yoo ṣe ṣe ọdun si. Iwọgile awọn ayẹyẹ Keresimesi ati opin ọdin gbogbo bii adura aisun ọdun, ayẹyẹ ọlọpọ ero Carnival, pẹlu ayẹyẹ wẹjẹwẹmu gbogbo. Lẹyin ti gomina ipinlẹ naa ti lugbadi aarun COVID ti iroyin si tun ti n fihan pe iye awọn to n ko aarun naa lojoojumọ tunt ti n peleke sii gẹgẹ bi awọn agbejade ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun lorilẹede Naijiria, NCDC ṣe n gbe e jade lojojumọ ni Gomina Babajide Sanwo-Olu ti gbe awọn ilana akọtun sita ti yoo de bi ọrs pọpọṣin'sin ọdun yoo ṣe lọ ni ipinlẹ naa. Lara awọn ilana to gbe kalẹ ree. Laipẹ yii ni awọn oluwadi ijinlẹ nipa kokoro arun ni ibudo iwadi imọ igbalode nipa kokoro arun to wa lọgba fasiti Redeemers University ni ilu Ẹdẹ pariwo sita pe o jọ bi ẹni pe ẹya tuntun kokoro aarun COVID-19 ti wọ ipinlẹ Ọṣun eleyi to ko jinijini bo ọpọ. Ijọba ipinlẹ naa gbe awọn ilana kan kalẹ lati rii daju pe wahala ajakalẹ arun naa ko tun burẹkẹ lẹẹkeji. Ipinlẹ Ekiti naa ko gbẹyin ninu igbesẹ ilana lati wa ọwọ ajakalẹ arun COVID-19 to tun fẹ maa gbẹnu soke bayii bọlẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-55436758 |
1entertainment
| Cardi B leaked video: Cardi B ṣàlàyé ohun tó gbé fọ́tò ìhòhò rẹ̀ d'órí ayélujára Instagram | Onkọrin, ọmọ ilẹ America, Cardi B ti fesi lẹyin to ṣe e ṣi fi fọto ihoho rẹ sori ayelujara Instagram rẹ. Akọrin takasufe naa to ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mejidinlọgbọn rẹ lọjọ Aiku, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa, sare lati yọ fọto naa kuro lori ayelujara. Ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, nitori pe nigba ti yoo fi yi oju foonu rẹ pada si ibi to yẹ, fọto naa ti lọ sori Instagram, awọn ololufẹ rẹ to ju miliọnu mẹrindinlọgọrin lọ, si ti ri ihoho rẹ. Niṣe ni Cardi B sare pa fọto naa rẹ, to si gba pe oun ṣe aṣiṣe. Lẹyin naa lo sọ pe oun ko ni i gbe ẹnikẹni lọ sile ẹjọ lori fidio ihoho naa, nitori pe ọwọ oun ni aṣiṣe naa ti wa. Bakan naa lo ni oun ko ni tori rẹ bara jẹ. Ko tan sibẹ o, akọrin takasufe naa ṣalaye pe oun ati ọkọ oun, Offset, lo jọ n ya fọto nigba ti oun ṣe e ṣi tẹ bọtini miran, to si gbe e lọ sori ayelujara Instagram. O gbiyanju lati yara pa foonu naa lati da fọto naa duro, ṣugbọn o ti pẹ ju. Yoruba bọ, wọn ni isọrọ nigbesi. Cardi tun fun ẹnikan to gbiyanju lati bu ẹnu atẹ lu irisi rẹ ninu fọto naa, l'esi pe "ori ọyan mi tobi, nitori pe mo fun ọmọ mi, Kulture l'ọmu fun oṣu mẹta". Awọn ololufẹ Cardi B si ti bẹrẹ si ni i ṣe atilẹyin fun un lẹyin iṣẹlẹ naa. Awọn kan ti ẹ tun n fi fọto ihoho wọn sita pẹlu #BoobsOutForCardi. | Cardi B leaked video: Cardi B ṣàlàyé ohun tó gbé fọ́tò ìhòhò rẹ̀ d'órí ayélujára Instagram Onkọrin, ọmọ ilẹ America, Cardi B ti fesi lẹyin to ṣe e ṣi fi fọto ihoho rẹ sori ayelujara Instagram rẹ. Akọrin takasufe naa to ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mejidinlọgbọn rẹ lọjọ Aiku, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa, sare lati yọ fọto naa kuro lori ayelujara. Ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, nitori pe nigba ti yoo fi yi oju foonu rẹ pada si ibi to yẹ, fọto naa ti lọ sori Instagram, awọn ololufẹ rẹ to ju miliọnu mẹrindinlọgọrin lọ, si ti ri ihoho rẹ. Niṣe ni Cardi B sare pa fọto naa rẹ, to si gba pe oun ṣe aṣiṣe. Lẹyin naa lo sọ pe oun ko ni i gbe ẹnikẹni lọ sile ẹjọ lori fidio ihoho naa, nitori pe ọwọ oun ni aṣiṣe naa ti wa. Bakan naa lo ni oun ko ni tori rẹ bara jẹ. Ko tan sibẹ o, akọrin takasufe naa ṣalaye pe oun ati ọkọ oun, Offset, lo jọ n ya fọto nigba ti oun ṣe e ṣi tẹ bọtini miran, to si gbe e lọ sori ayelujara Instagram. O gbiyanju lati yara pa foonu naa lati da fọto naa duro, ṣugbọn o ti pẹ ju. Yoruba bọ, wọn ni isọrọ nigbesi. Cardi tun fun ẹnikan to gbiyanju lati bu ẹnu atẹ lu irisi rẹ ninu fọto naa, l'esi pe "ori ọyan mi tobi, nitori pe mo fun ọmọ mi, Kulture l'ọmu fun oṣu mẹta". Awọn ololufẹ Cardi B si ti bẹrẹ si ni i ṣe atilẹyin fun un lẹyin iṣẹlẹ naa. Awọn kan ti ẹ tun n fi fọto ihoho wọn sita pẹlu #BoobsOutForCardi. | https://www.bbc.com/yoruba/media-54565896 |
4religion
| Aheregbe and Amole festival in Akure: Ojú aráàlú rí màbo pẹ̀lú báwọn jàǹdùkú ṣe sọ àjọ̀dún Amole di 'ọdún olè jíjà' nílùú Akure | Ibinu ati ẹhonu lo tẹle ayẹyẹ ọdun Amọle, iyẹn ọdun iṣẹṣe ilu Akurẹ to waye lọjọbọ, ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2021. Gẹgẹbi iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ kaakiri awọn agbegbe ilu Akurẹ lasiko ọdun naa ṣe sọ, ọpọ iwa ole, ijinigbe ati idaluru lo waye lasiko ọdun naa ti awọn janduku kan si n fọwọ lalẹ pe awọn lẹtọ lati ṣe bẹ labẹ iboju ọdun naa. Fun apẹrẹ, lasiko ajọdun naa, nṣe lawọn janduku kan kọlu awọn eeyan lagbegbe Bọlajoko Junction ni Oke Aro ni opopona Idanre. Awọn janduku naa di ọna mọ ọkọ bọọsi kan to ko ounjẹ atawọn ohun elo ile miran ti wọn si ji gbogbo ohun to wa ninu rẹ lọ. Bakan naa lawọn oju mi too kan tun ṣalaye ohun ti oju ri awọn janduku kan ti wọn ni awọn n fi idi 'ofin maa ta ọja" ti aafin Ọba Deji ti ilu Akurẹ pa pe ko gbọdọ si ṣiṣi ọja lọjọ ọdun Aheregbe ati Amọle naa mulẹ ni ṣe fi tipa gbe ọmọ okunrin aṣoju ileeṣẹ itaja kan ti wọn si tun jo taya ọkọ rẹ. Okunrin naa gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin abẹle kan nilu Akurẹ ṣe sọ, arakunrin naa n gbe ọmọ rẹ lọ sileewe lasiko ti awọn janduku naa da lọna ti wọn si ko gbogbo ọja ileeṣẹ rẹ to ko sinu ọkọ. Gbogbo bi arakunrin naa ṣe n pariwo pe oun ko ta ọja, ọmọ oun loun n gbe lọ sileewe ko tu irun kan lara awọn eeyan naa, koda wọn tun gbe ọmọ rẹ naa pẹlu. Awọn aladugbo lagbegbe naa lo fariga tẹle awọn janduku ọhun lati gba ọmọ rẹ pada. Ni Ọjọru ni atẹjade kan jade lati afin Ọba Deji ti ilu Akurẹ pe ayẹyẹ ọdun aheregbe ati amọle yoo waye, nitorina ki wọn ọja ati ṣọọbu ko wa ni titi pa. Amọṣa atẹjade naa ko sọ pe ki ẹnikẹni o maa jade tabi rin loju popo. | Aheregbe and Amole festival in Akure: Ojú aráàlú rí màbo pẹ̀lú báwọn jàǹdùkú ṣe sọ àjọ̀dún Amole di 'ọdún olè jíjà' nílùú Akure Ibinu ati ẹhonu lo tẹle ayẹyẹ ọdun Amọle, iyẹn ọdun iṣẹṣe ilu Akurẹ to waye lọjọbọ, ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2021. Gẹgẹbi iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ kaakiri awọn agbegbe ilu Akurẹ lasiko ọdun naa ṣe sọ, ọpọ iwa ole, ijinigbe ati idaluru lo waye lasiko ọdun naa ti awọn janduku kan si n fọwọ lalẹ pe awọn lẹtọ lati ṣe bẹ labẹ iboju ọdun naa. Fun apẹrẹ, lasiko ajọdun naa, nṣe lawọn janduku kan kọlu awọn eeyan lagbegbe Bọlajoko Junction ni Oke Aro ni opopona Idanre. Awọn janduku naa di ọna mọ ọkọ bọọsi kan to ko ounjẹ atawọn ohun elo ile miran ti wọn si ji gbogbo ohun to wa ninu rẹ lọ. Bakan naa lawọn oju mi too kan tun ṣalaye ohun ti oju ri awọn janduku kan ti wọn ni awọn n fi idi 'ofin maa ta ọja" ti aafin Ọba Deji ti ilu Akurẹ pa pe ko gbọdọ si ṣiṣi ọja lọjọ ọdun Aheregbe ati Amọle naa mulẹ ni ṣe fi tipa gbe ọmọ okunrin aṣoju ileeṣẹ itaja kan ti wọn si tun jo taya ọkọ rẹ. Okunrin naa gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin abẹle kan nilu Akurẹ ṣe sọ, arakunrin naa n gbe ọmọ rẹ lọ sileewe lasiko ti awọn janduku naa da lọna ti wọn si ko gbogbo ọja ileeṣẹ rẹ to ko sinu ọkọ. Gbogbo bi arakunrin naa ṣe n pariwo pe oun ko ta ọja, ọmọ oun loun n gbe lọ sileewe ko tu irun kan lara awọn eeyan naa, koda wọn tun gbe ọmọ rẹ naa pẹlu. Awọn aladugbo lagbegbe naa lo fariga tẹle awọn janduku ọhun lati gba ọmọ rẹ pada. Ni Ọjọru ni atẹjade kan jade lati afin Ọba Deji ti ilu Akurẹ pe ayẹyẹ ọdun aheregbe ati amọle yoo waye, nitorina ki wọn ọja ati ṣọọbu ko wa ni titi pa. Amọṣa atẹjade naa ko sọ pe ki ẹnikẹni o maa jade tabi rin loju popo. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58278046 |
2health
| World Cancer Day: Ènìyàn 26,000 ni àìsàn jẹjẹrẹ ń pa lóòjọ́ | Ajọ Eto Ilera Lagbaye, WHO ti pe akiyesi awọn eniyan si ipa ti aisan jẹjẹrẹ n ko lawujọ, pẹlu akiyesi pe miliọnu mẹjọ eniyan ni yoo ku lọdun yii nipa aisan jẹjẹrẹ. Ajọ Agbaye to ni akọri ti ọdun yii ni 'I am and I will', fikun wi pe ẹgbẹrun mẹrinlelọgbọn eniyan lo n ku lojoojumọ nitori aisan jẹjẹrẹ. Ajọ naa fikun wi pe o ṣeeṣẹ ki o peleke si ninu ọdun yii pẹlu bi oju ọjọ ṣe n bajẹ si, ti igbe aye awọn eniyan o gbe pẹẹli si ati iru ounjẹ ti awọn eniyan n jẹ. Àkójọpọ̀ àwòrán láti ìpàdé ìtagbangba pẹ̀lú àwọn olùdije ní Ọyọ Àwọn ohun mánigbàgbé níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Ọyọ Èwo nínú ìlérí tí Buhari ṣe ní 2015 ló ti mú ṣẹ? Gbọ̀ngàn Mapo, ọ̀kan lára ibi àmúyangàn n'Ibadan rèé Link Mímu ọtí líle àti oúnjẹ oní sítáṣì le è fa àrùn jẹjẹrẹ ọyàn - Onímọ̀ Àgbálùmọ̀, ohun mẹ́fà tó ń ṣe lára tí o kò mọ̀ Àwọn àwòrán ẹ̀yìn ìtàgé níbi ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Eko Day 19: Wo ohun àràmàndà tí àwọn olósèlú máa ń ṣe lásìkò ìbò #BBCNigeria2019 Sowore: olùdíje Ààrẹ tó fẹ gbà Nàìjíríà padà fún àwọn ọdọ | World Cancer Day: Ènìyàn 26,000 ni àìsàn jẹjẹrẹ ń pa lóòjọ́ Ajọ Eto Ilera Lagbaye, WHO ti pe akiyesi awọn eniyan si ipa ti aisan jẹjẹrẹ n ko lawujọ, pẹlu akiyesi pe miliọnu mẹjọ eniyan ni yoo ku lọdun yii nipa aisan jẹjẹrẹ. Ajọ Agbaye to ni akọri ti ọdun yii ni 'I am and I will', fikun wi pe ẹgbẹrun mẹrinlelọgbọn eniyan lo n ku lojoojumọ nitori aisan jẹjẹrẹ. Ajọ naa fikun wi pe o ṣeeṣẹ ki o peleke si ninu ọdun yii pẹlu bi oju ọjọ ṣe n bajẹ si, ti igbe aye awọn eniyan o gbe pẹẹli si ati iru ounjẹ ti awọn eniyan n jẹ. Àkójọpọ̀ àwòrán láti ìpàdé ìtagbangba pẹ̀lú àwọn olùdije ní Ọyọ Àwọn ohun mánigbàgbé níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Ọyọ Èwo nínú ìlérí tí Buhari ṣe ní 2015 ló ti mú ṣẹ? Gbọ̀ngàn Mapo, ọ̀kan lára ibi àmúyangàn n'Ibadan rèé Link Mímu ọtí líle àti oúnjẹ oní sítáṣì le è fa àrùn jẹjẹrẹ ọyàn - Onímọ̀ Àgbálùmọ̀, ohun mẹ́fà tó ń ṣe lára tí o kò mọ̀ Àwọn àwòrán ẹ̀yìn ìtàgé níbi ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Eko Day 19: Wo ohun àràmàndà tí àwọn olósèlú máa ń ṣe lásìkò ìbò #BBCNigeria2019 Sowore: olùdíje Ààrẹ tó fẹ gbà Nàìjíríà padà fún àwọn ọdọ | https://www.bbc.com/yoruba/47113701 |
5sports
| Fulham vs Arsenal: Arsenal lu Fulham ní àlùbami pẹ̀lú 3-0, ṣùgbọ́n ariwo Willian layé ń pa | Nnkan o rọgbọ fun ikọ Fulham ni ipadabọ wọn si idije Premier league ilẹ Gẹẹsi lọjọ Satide pẹlu bi Arsenal ti wọn gba lalejo din dundu iya ni adingbẹ fun wọn ni papa iṣire Craven Cottage to jẹ ibuba wọn. Goolu mẹta si odo ni Arsenal fi ki ikọ Fulham to ṣẹṣẹ gba igbega wa si premier league lati liigi keji ilẹ Gẹẹsi ti a mọ si Championships kaabọ. Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju mẹsan ni atamatase agbabọọlu ikọ Arsenal, Lacazette lo gba goolu akọkọ wọle fun Arsenal eleyi to fun un ni iyi ẹni to gba goolu akọkọ wọle fun saa liigi tọdun 2020/2021 to bẹrẹ lọjọ Abamẹta. Bakan naa ni goolu ọhun tun sọ Lacazette di agbabọọlu akọkọ ninu itan premier league ti yoo maa gba goolu akọkọ ni saa liigi kan wọle fun saa liigi meji ọtọọtọ. Ni saa liigi ọdun 2017/2018, Lacazette ni agbabọọlu to gba goolu akọkọ wọle lọdun naa ninu ifẹsẹwọnsẹ Arsenal pẹlu Leicester Agbabọọlu ti Arsenal ṣẹṣẹ ra ni ọsẹ diẹ sẹyin, Gabriel Magalhaesjẹwọ pe Arsenal ko fowo jona pẹlu bi o ṣe gba goolu rẹ akọkọ wọle fun ikọ Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ naa eleyi to jẹ ifẹsẹwọnsẹ liigi akọkọ ti yoo ti kopa fun Arsenal. Ni kete ti wọn wọle ni Gabriel ti fori gbe bọọlu gbee silẹ ni igun papa koo gba, iyẹn Corner ti Willian, agbabọọlu tuntun miran ti Arsenal ra lati Chelsea gba soju ile Fulham nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kọkandinlaadọta. Gẹgẹ bi iṣe rẹ, balogun ikọ Arsenal, Pierre-Emerick Aubameyang naa da si ojo goolu to rọ fun Arsenal ni papa iṣire Craven Cottage nigba ti oun naa sọ goolu kẹta sawọn fun Arsenal nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtadinlọgọta. Pẹlu goolu yii, Aubameyang ti gba goolu mọkanla wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ mọkanla ni ṣiṣẹ n tẹle to ti gba fun Arsenal. Ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ ni ni aworan ija laarin agbabọọlu Arsenal meji, Ceballous ati Nketiah ti waye lasiko ti wọn fi n gbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ naa ni papa iṣire Craven Cottage ti ifẹsẹwọnsẹ naa ti waye. Awọn agbabọọlu mejeeji yii wa lara awọn ti akọnimọọgba ikọ naa, Mikel Arteta mu lati rọpo awọn agbabọọlu to ba yọ lori papa bi ifẹsẹwọnsẹ naa ba ṣe n lọ | Fulham vs Arsenal: Arsenal lu Fulham ní àlùbami pẹ̀lú 3-0, ṣùgbọ́n ariwo Willian layé ń pa Nnkan o rọgbọ fun ikọ Fulham ni ipadabọ wọn si idije Premier league ilẹ Gẹẹsi lọjọ Satide pẹlu bi Arsenal ti wọn gba lalejo din dundu iya ni adingbẹ fun wọn ni papa iṣire Craven Cottage to jẹ ibuba wọn. Goolu mẹta si odo ni Arsenal fi ki ikọ Fulham to ṣẹṣẹ gba igbega wa si premier league lati liigi keji ilẹ Gẹẹsi ti a mọ si Championships kaabọ. Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju mẹsan ni atamatase agbabọọlu ikọ Arsenal, Lacazette lo gba goolu akọkọ wọle fun Arsenal eleyi to fun un ni iyi ẹni to gba goolu akọkọ wọle fun saa liigi tọdun 2020/2021 to bẹrẹ lọjọ Abamẹta. Bakan naa ni goolu ọhun tun sọ Lacazette di agbabọọlu akọkọ ninu itan premier league ti yoo maa gba goolu akọkọ ni saa liigi kan wọle fun saa liigi meji ọtọọtọ. Ni saa liigi ọdun 2017/2018, Lacazette ni agbabọọlu to gba goolu akọkọ wọle lọdun naa ninu ifẹsẹwọnsẹ Arsenal pẹlu Leicester Agbabọọlu ti Arsenal ṣẹṣẹ ra ni ọsẹ diẹ sẹyin, Gabriel Magalhaesjẹwọ pe Arsenal ko fowo jona pẹlu bi o ṣe gba goolu rẹ akọkọ wọle fun ikọ Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ naa eleyi to jẹ ifẹsẹwọnsẹ liigi akọkọ ti yoo ti kopa fun Arsenal. Ni kete ti wọn wọle ni Gabriel ti fori gbe bọọlu gbee silẹ ni igun papa koo gba, iyẹn Corner ti Willian, agbabọọlu tuntun miran ti Arsenal ra lati Chelsea gba soju ile Fulham nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kọkandinlaadọta. Gẹgẹ bi iṣe rẹ, balogun ikọ Arsenal, Pierre-Emerick Aubameyang naa da si ojo goolu to rọ fun Arsenal ni papa iṣire Craven Cottage nigba ti oun naa sọ goolu kẹta sawọn fun Arsenal nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtadinlọgọta. Pẹlu goolu yii, Aubameyang ti gba goolu mọkanla wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ mọkanla ni ṣiṣẹ n tẹle to ti gba fun Arsenal. Ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ ni ni aworan ija laarin agbabọọlu Arsenal meji, Ceballous ati Nketiah ti waye lasiko ti wọn fi n gbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ naa ni papa iṣire Craven Cottage ti ifẹsẹwọnsẹ naa ti waye. Awọn agbabọọlu mejeeji yii wa lara awọn ti akọnimọọgba ikọ naa, Mikel Arteta mu lati rọpo awọn agbabọọlu to ba yọ lori papa bi ifẹsẹwọnsẹ naa ba ṣe n lọ | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-54129859 |
3politics
| Tinubu ló sanwó ta fi gbé òkú Moji Olaiya wá láti òke òkun - Jide Kosoko | Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọmọ ẹni kò ní ṣe ìdí bẹ̀bẹ̀rẹ̀ kákó ìlẹ̀kẹ̀ sídìí ọmọ ẹlòmíràn. Nínú ọ̀sẹ̀ yìí ni fídíò kan gba orí ayélujára tó ṣàfihàn àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ nínú eré tíátà Yorùbá níbi tí wọ́n ti ń ṣe àtìlẹyìn fún olùdíje sípò Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu. Lára àwọn tó wà nínú fídíò náà ni Jide Kosoko, Adebayo Salami, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí ọga Bello, Foluke Daramola, Fausa Balogun, Yinka Quadri, Taiwo Haasan Ogogo, Iya Awero àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Fídíò yìí ló ti ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye lórí ayélujára pàápàá láàárín àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń sọ wí pé kò yẹ kí àwọn àgbà òṣèré máa fi ipò wọn ṣe ìpolongo fún àwọn olóṣèlú. Ẹ̀wẹ̀, nígbà tí Jide Kosoko ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ó ní ipa tí Tinubu ti kó nínú ìgbésí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣèré tíátà kò ṣé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá. Kosoko ní Tinubu kìí kan ṣe olórí lásán bíkòṣe aláàánú, tó fi ọrọ̀ rẹ̀ mọ àwọn òṣèré tíátà náà. Ó ní ìdí nìyí tí àwọn náà fi ń gbá rùkù tìí, tí àwọn sì ń ṣe ìpolongo fún-un. “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni Asiwaju ti fa lọ́wọ́ sókè nínú eré tíátà pàápàá àwọn tó bá ní ìpèníjà ìlera”. “Nígbà tí Moji Olaiya kú sí orílẹ̀ èdè Canada, Tinubu ló san gbogbo owó tí wọ́n fi gbé òkú rẹ̀ wá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.” Bákan náà ló ní ìyàwó Tinubu náà ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfàní fún ọ̀kan-ò-jọ̀kan ènìyàn nínú eré tíátà tí àwọn kò le kà tán. Fídíò yìí ló ti ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye lórí ayélujára pàápàá láàárín àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń sọ wí pé kò yẹ kí àwọn àgbà òṣèré máa fi ipò wọn ṣe ìpolongo fún àwọn olóṣèlú. Ẹ̀wẹ̀, nígbà tí Jide Kosoko ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ó ní ipa tí Tinubu ti kó nínú ìgbésí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣèré tíátà kò ṣé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá. Kosoko ní Tinubu kìí kan ṣe olórí lásán bíkòṣe aláàánú, tó fi ọrọ̀ rẹ̀ mọ àwọn òṣèré tíátà náà. Ó ní ìdí nìyí tí àwọn náà fi ń gbá rùkù tìí, tí àwọn sì ń ṣe ìpolongo fún-un. “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni Asiwaju ti fa lọ́wọ́ sókè nínú eré tíátà pàápàá àwọn tó bá ní ìpèníjà ìlera”. “Nígbà tí Moji Olaiya kú sí orílẹ̀ èdè Canada, Tinubu ló san gbogbo owó tí wọ́n fi gbé òkú rẹ̀ wá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.” Bákan náà ló ní ìyàwó Tinubu náà ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfàní fún ọ̀kan-ò-jọ̀kan ènìyàn nínú erér tíátà tí àwọn kò le kà tán. | Tinubu ló sanwó ta fi gbé òkú Moji Olaiya wá láti òke òkun - Jide Kosoko Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọmọ ẹni kò ní ṣe ìdí bẹ̀bẹ̀rẹ̀ kákó ìlẹ̀kẹ̀ sídìí ọmọ ẹlòmíràn. Nínú ọ̀sẹ̀ yìí ni fídíò kan gba orí ayélujára tó ṣàfihàn àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ nínú eré tíátà Yorùbá níbi tí wọ́n ti ń ṣe àtìlẹyìn fún olùdíje sípò Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu. Lára àwọn tó wà nínú fídíò náà ni Jide Kosoko, Adebayo Salami, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí ọga Bello, Foluke Daramola, Fausa Balogun, Yinka Quadri, Taiwo Haasan Ogogo, Iya Awero àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Fídíò yìí ló ti ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye lórí ayélujára pàápàá láàárín àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń sọ wí pé kò yẹ kí àwọn àgbà òṣèré máa fi ipò wọn ṣe ìpolongo fún àwọn olóṣèlú. Ẹ̀wẹ̀, nígbà tí Jide Kosoko ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ó ní ipa tí Tinubu ti kó nínú ìgbésí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣèré tíátà kò ṣé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá. Kosoko ní Tinubu kìí kan ṣe olórí lásán bíkòṣe aláàánú, tó fi ọrọ̀ rẹ̀ mọ àwọn òṣèré tíátà náà. Ó ní ìdí nìyí tí àwọn náà fi ń gbá rùkù tìí, tí àwọn sì ń ṣe ìpolongo fún-un. “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni Asiwaju ti fa lọ́wọ́ sókè nínú eré tíátà pàápàá àwọn tó bá ní ìpèníjà ìlera”. “Nígbà tí Moji Olaiya kú sí orílẹ̀ èdè Canada, Tinubu ló san gbogbo owó tí wọ́n fi gbé òkú rẹ̀ wá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.” Bákan náà ló ní ìyàwó Tinubu náà ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfàní fún ọ̀kan-ò-jọ̀kan ènìyàn nínú eré tíátà tí àwọn kò le kà tán. Fídíò yìí ló ti ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye lórí ayélujára pàápàá láàárín àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń sọ wí pé kò yẹ kí àwọn àgbà òṣèré máa fi ipò wọn ṣe ìpolongo fún àwọn olóṣèlú. Ẹ̀wẹ̀, nígbà tí Jide Kosoko ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ó ní ipa tí Tinubu ti kó nínú ìgbésí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣèré tíátà kò ṣé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá. Kosoko ní Tinubu kìí kan ṣe olórí lásán bíkòṣe aláàánú, tó fi ọrọ̀ rẹ̀ mọ àwọn òṣèré tíátà náà. Ó ní ìdí nìyí tí àwọn náà fi ń gbá rùkù tìí, tí àwọn sì ń ṣe ìpolongo fún-un. “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni Asiwaju ti fa lọ́wọ́ sókè nínú eré tíátà pàápàá àwọn tó bá ní ìpèníjà ìlera”. “Nígbà tí Moji Olaiya kú sí orílẹ̀ èdè Canada, Tinubu ló san gbogbo owó tí wọ́n fi gbé òkú rẹ̀ wá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.” Bákan náà ló ní ìyàwó Tinubu náà ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfàní fún ọ̀kan-ò-jọ̀kan ènìyàn nínú erér tíátà tí àwọn kò le kà tán. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cm5vj89m208o |
4religion
| Tithing: Daddy Freeze àtàwọn ọmọ Nàìjíríà míì ta gbá òjíṣẹ́ Ọlọ́run torí ègún ìdá mẹ́wàá | Ṣe ni ori ayelujara tun n gbona tori ọrọ ida mẹwaa ti olori ìjọ Living Faith, Bisọọbu David Oyedepo sọ ni ọjọ Ẹti. Bisọọbu Oyedepo, lo sọ loju opo Twitter rẹ pe egun ọda owo yoo ja ẹnikẹni ti ko ba da ida mẹwaa fun ijọ Ọlọrun. Oyedepo ni "Ida mẹwaa jẹ majẹmu pẹlu Ọlọrun ti ko ṣe e yẹ, laisi ida mẹwaa, ko see ṣe lati ṣe rere tabi ni ọrọ, aisan ida mẹwaa si lo n fi ẹ sinu egun ọda owo. Bakan naa lo fikun pe" ọna to n gba ṣe akoso ẹnawo rẹ ni yoo sọ bo ṣe lowo si nitori ọpọ isoro ti ẹda n koju la le e tọ ipasẹ rẹ de idi ibasepọ rẹ pẹlu owo. " Ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijiria to ka ọrọ yii lo faraya, ti wọn si ni irufẹ ọrọ bayii ko dara rara. Nigba to n fesi lori ọrọ Oyedepo naa, Ifedayo Olarinde, ti ọpọ eeyan mọ si Daddy Freeze ni ọrọ radarada ni ojisẹ Ọlọrun naa kọ, ti ko si bojumu. "Ṣe o ni ida kan owo ti awọn olowo agbaye bii Jeff Bezos, Bill Gates ati Warren Buffet, ti kii san ida mẹwaa ni bi? Mo ri ọrọ yii bii eyi ti ko ba Bibeli mu, to si jẹ iwa ika si ọmọniyan? Daddy Freeze ni Jesu tabi awọn ọmọ ẹyin rẹ ko gba ida mẹwaa nigba aye rẹ, ofin atijọ ni sisan ida mẹwaa jẹ, idi si ree ti Kristẹni fi n pe ofin majẹmu laelae ni ofin ẹsẹ ati iku. Ẹ yé tako ìjọba lórí iléèjọ́sìn títì pa, ẹ jọ̀wọ́ ṣọ́ọ̀ṣì yín fún ìtọ́jú àwọn tó lárùn coronavirus- Tunde Bakare Oludasilẹ ijọ Latter Rain Assembly, Tunde Bakare ti rọ awọn alufa ijọ bi tiẹ lati jọwọ gbọngan ile ijọsin silẹ fun ijọba lati loo fun ibudo itọju awọn alaisan coronavirus. Pasitọ Bakare sọrọ yii ninu fidio kan to wa lori ayelujara eleyi tawọn eeyan ti n sọrọ nipa rẹ. Pasitọ Bakare ni ijọ Latter Rain gan an ti jọwọ gọngan meji to jẹ ti ṣọọṣi naa fun ijọba ipinlẹ Eko lati lo fun ibudo iyasọtọ awọn to ti lugbadi coronavirus. Bakan naa lo sọ pe ijọ naa tun ti jọwọ ile kan niluu Abẹokuta fun ijọba ipinlẹ Ogun lati lo fun itọju awọn to laarun covid-19. O bu ẹnu atẹ lu awọn ojiṣẹ Ọlọrun kan ti wọn sọ pe ko yẹ ki ọja wa ni ṣiṣi nigba ile ijọsin wa ni titipa. Alufaa Bakare nisẹ lo yẹ kawọn ojiṣẹ Ọlọrun ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba lati gbogun ti ajakalẹ aarun coronavirus to n ba gbogbo aye finra lọwọ yii. O ni o yẹ kawọn ile ijọsin nla jọwọ lo ohun ini wọn lati ran ijọba lọwọ, dipọ kawọn olori wọn maa tako igbesẹ ijọba lori ofin konle-o-gbele. Pasitọ Bakare ni ṣọọṣi nikan kọ ni ijọba fofin de, o ni o kan mọṣalaaṣi naa. O ṣalaye pe ijọba ko gbe ọja tipa nitori ki ebi maa ba pa ọgọrọ araalu to jọ pe iṣẹ oojọ ni wọn n ṣe ki wọn to le jẹun. Alufaa Bakare lu awọn oṣiṣẹ eleto ilera lọgọ ẹnu lori iṣẹ takun takun ti wọn n ṣe lasiko ajakalẹ coronavirus yii, o gbadura fun aabo Ọlọrun lori wọn. Èrò ọmọ Nàìjíríà ṣ'ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Bíṣọ́ọ́bù Oyedepo pé kò sí ìdí tí iléèjọ́sìn láti wà ní títì pa Bisọọbu David Oyedepo, nínú ìsìn irọlẹ Ọjọru faraya lórí bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ti ilẹkun mọ àwọn sọọsi àmọ́ tó ń sì àwọn ọjà oúnjẹ gbogbo fún wákàtí mẹ́fà gbáko, nibiti àwọn aráàlú kò ti bọ̀wọ̀ fún òfin títa kété síra ẹni.Ọ̀rọ̀ ojisẹ Ọlọ́run náà sì lo tí ń fa awuyewuye làwọn ojú òpó ikansiraẹni lórí itakun àgbáyé , bí àwọn èèyàn kan sì ṣe tako èrò rẹ, ni àwọn míràn fara mọ.Kódà, ọ̀rọ̀ náà kò tíì tán lójú òpó BBC Yoruba, nibiti àwọn èèyàn ti ń gbáà ọrọ náà mọ ara wọn lọ́wọ́, bíi ẹni gba igba ọtí. Lérò tí Ajayi Solomon, oúnjẹ leè gbé ẹmi ró gẹ́gẹ́ bíi ẹlẹ́ran ara àmọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan ni oúnjẹ ẹ̀mí tí yóò jẹ ká dàgbà nínú ìwà rere, tí yóò sì jẹ ká ye, ó ní ọjà àti sọọsi lo yẹ kí ìjọba sí papọ. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló tako èrò rẹ yìí, ní èrò tí Nurudeen Mufc Bamidele, kò sì ibi tí èèyàn kò ti leè gbọ ọrọ Ọlọ́run, tí Dára Dariz Ogunsola náà sì kin lẹ́yìn pé oúnjẹ kii wọnú, kí ọrọ miran wọ ọ, bí àwọn èèyàn kò bá jẹun, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò leè wọ wọn létí. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó sì dá sí ìjíròrò náà lo fara mọ pe oúnjẹ ní kókó, kódà, Oluwaseun Abiodun ni, niwọn ìgbà tí àwọn ilé ìjọsìn kò ní fún àwọn ni oúnjẹ jẹ, ọjà tí àwọn yoo ti rí oúnjẹ rà ni pàtàkì. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn míràn yí ọ̀rọ̀ náà si ibòmíràn, tí wọ́n sì ni torí owó tí àwọn ìjọ Ọlọ́run kò rí pa wọlé mọ, ní ojisẹ Ọlọ́run náà ṣe ń pariwo lórí bí ìjọba ṣe tí ilé ìjọsìn pá. Afolabi Idris Wayforward ń tiẹ̀ ń béèrè pé kí ló dé tí Oyedepo fi fẹ́ kí jọba si sọọsi pẹ̀lú tipátipá, ṣe nítorí owó tí kò wọlé fún àwọn ojisẹ Ọlọ́run mọ ni? Ìmọ̀ràn tí àwọn èèyàn mìíràn bíi Ojo Omoniyi wá ń gba aráàlú ni pé, bí wọn ṣe gba wọn láàyè láti lọ sí ọjà, ṣe ni kí wọn tẹle òfin títa kété síra ẹni, kí a máa bàa wá jẹbi lẹ́yìn ó rẹyìn. Oyedepo, ẹni tó pariwo bẹẹ lásìkò ìsìn wákàtí àdúrà tó wáyé ní Ọjọru ni, òun fura pé ejò lọ́wọ́ nínú lórí bí ìjọba kò ṣe tíì pàṣẹ láti ṣílẹ̀kùn ilé Ọlọ́run padà. "Ẹ ní kí wọn máa ṣílẹ̀kùn ọjà gbogbo fún wákàtí mẹ́fà, kí wá lo dé tí ẹ kò fi silẹkun sọọsi fún wákàtí méjì, mo ní ìgbàgbọ́ pé iditẹ mọ ìdàgbàsókè àwọn sọọsi ni Nàìjíríà ni èyí". "Mo ń fura pupọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ọlọ́run bá mi sọ̀rọ̀ púpọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ naa ni àná, àbí ọ̀nà wo ni wọn tún fẹ́ gbà láti dá sọọsi lọwọkọ kò má baa gbòòrò, oyè èyí kò ye àwọn èèyàn ti ọ̀rọ̀ yìí kan." Oyedepo ni ohùn òkùnkùn lo fẹ́ ń darí àwọn èèyàn ní gbogbo ẹ̀ka yìí, tó sì dojú kọ ìjọ Ọlọ́run nítorí bí àwọn sọọsi ṣe ń gbòòrò lo ń fọ èṣù lórí, àmọ́ ẹnu ọ̀nà ọrùn àpáàdì kò ní borí, Èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ yóò jìyà rẹ. Oyedepo tún wà ń béèrè pé" irú ilé ìwòsàn wo ló ń ṣe àṣeyọrí ìwòsàn bíi èyí táwọn ìjọ Ọlọ́run ńṣe? Ó ní ilé ìwòsàn tí àwọn èèyàn ń kú sí wa ni ṣíṣí silẹ àmọ́ wọn ti ilẹ̀kùn ilé Ọlọ́run nítorí ìwà ìjẹgàba Èṣù, èyí tí kò ní ìwòsàn. Irọ lasan ni, iroyin ofege lawọn eeyan kan n gbe kaakiri. Olu ileeṣẹ ilẹ Amẹrika ti fesi si si iroyin to lu oju ayelujara pa laarọ ọjọ Ẹti pe wọn o fun oludasilẹ ijọ Living Faith Church ti ọpọ mọ si Winners, Bisọọbu David Oyedepo. Iwe iroyin Thisday lo kọkọ gbe iroyin naa pe olu ile iṣẹ ilẹ Amẹrika ni Naijiria kọ lati fun Bisọbu ni fisa. Amọ olu ileeṣẹ ilẹ Amẹrika ṣalaye loju opo Twitter wọn pe irọ funfun balau ni iroyin naa. Wọn rọ awọn eeyan ti wọn ti ri iroyin naa lori ayelujara wi pe ki wọ kọ eti kun sii nitotri kosi otitọ kankan nibẹ. Olu ileeṣẹ ilẹ Amẹrika sọ loju opo Twitter wọn pe iṣinilọna gbaa ni iroyin naa to jade. Ọpọ eeyan lo ti n sọrọ lori ayelujara lati aarọ ọjọ Ẹti lati igba ti iroyin naa ti jade. | Tithing: Daddy Freeze àtàwọn ọmọ Nàìjíríà míì ta gbá òjíṣẹ́ Ọlọ́run torí ègún ìdá mẹ́wàá Ṣe ni ori ayelujara tun n gbona tori ọrọ ida mẹwaa ti olori ìjọ Living Faith, Bisọọbu David Oyedepo sọ ni ọjọ Ẹti. Bisọọbu Oyedepo, lo sọ loju opo Twitter rẹ pe egun ọda owo yoo ja ẹnikẹni ti ko ba da ida mẹwaa fun ijọ Ọlọrun. Oyedepo ni "Ida mẹwaa jẹ majẹmu pẹlu Ọlọrun ti ko ṣe e yẹ, laisi ida mẹwaa, ko see ṣe lati ṣe rere tabi ni ọrọ, aisan ida mẹwaa si lo n fi ẹ sinu egun ọda owo. Bakan naa lo fikun pe" ọna to n gba ṣe akoso ẹnawo rẹ ni yoo sọ bo ṣe lowo si nitori ọpọ isoro ti ẹda n koju la le e tọ ipasẹ rẹ de idi ibasepọ rẹ pẹlu owo. " Ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijiria to ka ọrọ yii lo faraya, ti wọn si ni irufẹ ọrọ bayii ko dara rara. Nigba to n fesi lori ọrọ Oyedepo naa, Ifedayo Olarinde, ti ọpọ eeyan mọ si Daddy Freeze ni ọrọ radarada ni ojisẹ Ọlọrun naa kọ, ti ko si bojumu. "Ṣe o ni ida kan owo ti awọn olowo agbaye bii Jeff Bezos, Bill Gates ati Warren Buffet, ti kii san ida mẹwaa ni bi? Mo ri ọrọ yii bii eyi ti ko ba Bibeli mu, to si jẹ iwa ika si ọmọniyan? Daddy Freeze ni Jesu tabi awọn ọmọ ẹyin rẹ ko gba ida mẹwaa nigba aye rẹ, ofin atijọ ni sisan ida mẹwaa jẹ, idi si ree ti Kristẹni fi n pe ofin majẹmu laelae ni ofin ẹsẹ ati iku. Ẹ yé tako ìjọba lórí iléèjọ́sìn títì pa, ẹ jọ̀wọ́ ṣọ́ọ̀ṣì yín fún ìtọ́jú àwọn tó lárùn coronavirus- Tunde Bakare Oludasilẹ ijọ Latter Rain Assembly, Tunde Bakare ti rọ awọn alufa ijọ bi tiẹ lati jọwọ gbọngan ile ijọsin silẹ fun ijọba lati loo fun ibudo itọju awọn alaisan coronavirus. Pasitọ Bakare sọrọ yii ninu fidio kan to wa lori ayelujara eleyi tawọn eeyan ti n sọrọ nipa rẹ. Pasitọ Bakare ni ijọ Latter Rain gan an ti jọwọ gọngan meji to jẹ ti ṣọọṣi naa fun ijọba ipinlẹ Eko lati lo fun ibudo iyasọtọ awọn to ti lugbadi coronavirus. Bakan naa lo sọ pe ijọ naa tun ti jọwọ ile kan niluu Abẹokuta fun ijọba ipinlẹ Ogun lati lo fun itọju awọn to laarun covid-19. O bu ẹnu atẹ lu awọn ojiṣẹ Ọlọrun kan ti wọn sọ pe ko yẹ ki ọja wa ni ṣiṣi nigba ile ijọsin wa ni titipa. Alufaa Bakare nisẹ lo yẹ kawọn ojiṣẹ Ọlọrun ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba lati gbogun ti ajakalẹ aarun coronavirus to n ba gbogbo aye finra lọwọ yii. O ni o yẹ kawọn ile ijọsin nla jọwọ lo ohun ini wọn lati ran ijọba lọwọ, dipọ kawọn olori wọn maa tako igbesẹ ijọba lori ofin konle-o-gbele. Pasitọ Bakare ni ṣọọṣi nikan kọ ni ijọba fofin de, o ni o kan mọṣalaaṣi naa. O ṣalaye pe ijọba ko gbe ọja tipa nitori ki ebi maa ba pa ọgọrọ araalu to jọ pe iṣẹ oojọ ni wọn n ṣe ki wọn to le jẹun. Alufaa Bakare lu awọn oṣiṣẹ eleto ilera lọgọ ẹnu lori iṣẹ takun takun ti wọn n ṣe lasiko ajakalẹ coronavirus yii, o gbadura fun aabo Ọlọrun lori wọn. Èrò ọmọ Nàìjíríà ṣ'ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Bíṣọ́ọ́bù Oyedepo pé kò sí ìdí tí iléèjọ́sìn láti wà ní títì pa Bisọọbu David Oyedepo, nínú ìsìn irọlẹ Ọjọru faraya lórí bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ti ilẹkun mọ àwọn sọọsi àmọ́ tó ń sì àwọn ọjà oúnjẹ gbogbo fún wákàtí mẹ́fà gbáko, nibiti àwọn aráàlú kò ti bọ̀wọ̀ fún òfin títa kété síra ẹni.Ọ̀rọ̀ ojisẹ Ọlọ́run náà sì lo tí ń fa awuyewuye làwọn ojú òpó ikansiraẹni lórí itakun àgbáyé , bí àwọn èèyàn kan sì ṣe tako èrò rẹ, ni àwọn míràn fara mọ.Kódà, ọ̀rọ̀ náà kò tíì tán lójú òpó BBC Yoruba, nibiti àwọn èèyàn ti ń gbáà ọrọ náà mọ ara wọn lọ́wọ́, bíi ẹni gba igba ọtí. Lérò tí Ajayi Solomon, oúnjẹ leè gbé ẹmi ró gẹ́gẹ́ bíi ẹlẹ́ran ara àmọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan ni oúnjẹ ẹ̀mí tí yóò jẹ ká dàgbà nínú ìwà rere, tí yóò sì jẹ ká ye, ó ní ọjà àti sọọsi lo yẹ kí ìjọba sí papọ. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló tako èrò rẹ yìí, ní èrò tí Nurudeen Mufc Bamidele, kò sì ibi tí èèyàn kò ti leè gbọ ọrọ Ọlọ́run, tí Dára Dariz Ogunsola náà sì kin lẹ́yìn pé oúnjẹ kii wọnú, kí ọrọ miran wọ ọ, bí àwọn èèyàn kò bá jẹun, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò leè wọ wọn létí. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó sì dá sí ìjíròrò náà lo fara mọ pe oúnjẹ ní kókó, kódà, Oluwaseun Abiodun ni, niwọn ìgbà tí àwọn ilé ìjọsìn kò ní fún àwọn ni oúnjẹ jẹ, ọjà tí àwọn yoo ti rí oúnjẹ rà ni pàtàkì. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn míràn yí ọ̀rọ̀ náà si ibòmíràn, tí wọ́n sì ni torí owó tí àwọn ìjọ Ọlọ́run kò rí pa wọlé mọ, ní ojisẹ Ọlọ́run náà ṣe ń pariwo lórí bí ìjọba ṣe tí ilé ìjọsìn pá. Afolabi Idris Wayforward ń tiẹ̀ ń béèrè pé kí ló dé tí Oyedepo fi fẹ́ kí jọba si sọọsi pẹ̀lú tipátipá, ṣe nítorí owó tí kò wọlé fún àwọn ojisẹ Ọlọ́run mọ ni? Ìmọ̀ràn tí àwọn èèyàn mìíràn bíi Ojo Omoniyi wá ń gba aráàlú ni pé, bí wọn ṣe gba wọn láàyè láti lọ sí ọjà, ṣe ni kí wọn tẹle òfin títa kété síra ẹni, kí a máa bàa wá jẹbi lẹ́yìn ó rẹyìn. Oyedepo, ẹni tó pariwo bẹẹ lásìkò ìsìn wákàtí àdúrà tó wáyé ní Ọjọru ni, òun fura pé ejò lọ́wọ́ nínú lórí bí ìjọba kò ṣe tíì pàṣẹ láti ṣílẹ̀kùn ilé Ọlọ́run padà. "Ẹ ní kí wọn máa ṣílẹ̀kùn ọjà gbogbo fún wákàtí mẹ́fà, kí wá lo dé tí ẹ kò fi silẹkun sọọsi fún wákàtí méjì, mo ní ìgbàgbọ́ pé iditẹ mọ ìdàgbàsókè àwọn sọọsi ni Nàìjíríà ni èyí". "Mo ń fura pupọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ọlọ́run bá mi sọ̀rọ̀ púpọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ naa ni àná, àbí ọ̀nà wo ni wọn tún fẹ́ gbà láti dá sọọsi lọwọkọ kò má baa gbòòrò, oyè èyí kò ye àwọn èèyàn ti ọ̀rọ̀ yìí kan." Oyedepo ni ohùn òkùnkùn lo fẹ́ ń darí àwọn èèyàn ní gbogbo ẹ̀ka yìí, tó sì dojú kọ ìjọ Ọlọ́run nítorí bí àwọn sọọsi ṣe ń gbòòrò lo ń fọ èṣù lórí, àmọ́ ẹnu ọ̀nà ọrùn àpáàdì kò ní borí, Èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ yóò jìyà rẹ. Oyedepo tún wà ń béèrè pé" irú ilé ìwòsàn wo ló ń ṣe àṣeyọrí ìwòsàn bíi èyí táwọn ìjọ Ọlọ́run ńṣe? Ó ní ilé ìwòsàn tí àwọn èèyàn ń kú sí wa ni ṣíṣí silẹ àmọ́ wọn ti ilẹ̀kùn ilé Ọlọ́run nítorí ìwà ìjẹgàba Èṣù, èyí tí kò ní ìwòsàn. Irọ lasan ni, iroyin ofege lawọn eeyan kan n gbe kaakiri. Olu ileeṣẹ ilẹ Amẹrika ti fesi si si iroyin to lu oju ayelujara pa laarọ ọjọ Ẹti pe wọn o fun oludasilẹ ijọ Living Faith Church ti ọpọ mọ si Winners, Bisọọbu David Oyedepo. Iwe iroyin Thisday lo kọkọ gbe iroyin naa pe olu ile iṣẹ ilẹ Amẹrika ni Naijiria kọ lati fun Bisọbu ni fisa. Amọ olu ileeṣẹ ilẹ Amẹrika ṣalaye loju opo Twitter wọn pe irọ funfun balau ni iroyin naa. Wọn rọ awọn eeyan ti wọn ti ri iroyin naa lori ayelujara wi pe ki wọ kọ eti kun sii nitotri kosi otitọ kankan nibẹ. Olu ileeṣẹ ilẹ Amẹrika sọ loju opo Twitter wọn pe iṣinilọna gbaa ni iroyin naa to jade. Ọpọ eeyan lo ti n sọrọ lori ayelujara lati aarọ ọjọ Ẹti lati igba ti iroyin naa ti jade. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51328924 |
1entertainment
| Lizzy Anjorin: Èmi ń ṣiṣẹ́, obìnrin yìí ń gba owó láti fi ṣe àríyá | Iroyin nipa osere tiata ati onisowo nni, Lizzy Anjorin ati ọkọ rẹ lo tun n rugbo ni ori ayelujara lọwọ lọwọ bayii. Eyi ko si sẹyin bi obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Fola Tinubu se n pariwo Lizzy ati ọkọ rẹ, Alhaji Lawal lori ayelujara. Fola lo kede fawọn akọroyin lori ayelujara pe iya n jẹ oun, ti oun ko si nile lori nitori bi Lizzy Anjorin se gba ọkọ oun, to si bimọ fun. Bakan naa lo fun wọn ni ohun to gba silẹ nipa itakurọsọ lori foonu laarin ohun ati Alhaji Lawal yii, nibi to ti n beere pe ki onitọun fi owo ransẹ si oun. Eyi lo mu ki Lizzy wa se fidio kan soju opo Instagram rẹ, to fi n fun obinrin naa lesi pe oun ko ni orogun rara, nitori oun nikan ni iyawo ti ọkọ oun fẹ. Nigba to n sọrọ lori bi obinrin ọlọmọ mẹta naa se ni iya n jẹ oun, Lizzy wa se afihan bi obinrin naa se gba owo to le ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira laarin osu Januari nikan. "Fola, o kan bimọ fun ọkọ mi ni, o kii se iyawo rẹ rara nitori ko ba ọ se igbeyawo tabi so yigi fun ọ. Laarin osu kinni ọdun si akoko yii, owo to ti gba lọwọ ọkọ mi to miliọnu kan naira, to si tun lọ ba baba onile rẹ pe ko parọ pe o ko tii sanwo ile. Ti mo ba jẹ eeyan buruku ni, n ko ni jẹ ki ọkọ mi fun ọ ni owo tabi Jeep Exterra ti mo ni ki ọkọ mi gbe fun ọ, bẹẹ ni emi ni mo jẹ ki ọkọ mi gba oyun nigba to loyun." Bakan naa tun ni Lizzy se afihan agbasilẹ fọnran ohun itakurọsọ laarin ọkọ rẹ, Lawal ati Baba Onile naa, ti onitsun si n salaye pe obinrin naa lo ni ki oun parọ pe ko tii sanwo ile. Bakan naa ni Lizzy tako obinrin naa peirọ nla ni aworan to n gbe kiri pe oun se igbeyawo pẹlu ọkọ oun, nitori aworan naa ni wọn ya nigba ti wọn n fi obinrin naa joye. Lizzy wa n sọ fun obinrin naa pe to ba jẹ pe bi oun se ranti rẹ, naa lo jẹ ki Lawal ranti awọn eeyan to saaju tiẹ naa ni, ko ba ri wọn pe loni. O fikun pe kii kuku se pe Fola yii nilo owo amọ o mọọmọ se fọnran ohun naa sita lati wọ oun nilẹ ni, ti Ọlọrun yoo si gbe oun leke gbogbo wọn. Wayi o, Lizzy Anjorin ti sọ fun obinrin ti wọn dijọ n fa surutu naa pe fọọmu fun ayẹwo DNA ti wa nilẹ fun, to si se afihan awọn fọọmu naa. "Ọmọ mẹta lo sọ fun araye pe o bi fun wa, agbẹjọro yoo pe ọ ni ọjọbọ ọla, to ba lọ se DNA naa, ko to kuro nibẹ, maa fi owo ransẹ si ọ, ko lọ se tara rẹ naa, ko ma baa da bii magomago. To ba jẹ Lawal lo ni ọmọ mẹtẹẹta, a yanju rẹ amọ to ba jẹ ẹyọ kan tabi meji ni ti Lawal nibẹ, a maa ja." Nigba to n fesi lori bi awọn eeyan se n yọ suti ete si ọkọ rẹ pe owo osere tiata naa lo n na lai ni isẹ kan pato lọwọ, lizzy salaye pe okoowo jọ pa oun ati ọkọ oun pọ ni. "Lawal kii se Jigolo, ibudo to ti n ta mọto mẹta lo ni laarin Lekki si Ajah, to si tun ni ileesẹ ti wọn ti n fọ ọkọ. Lawal n sisẹ takuntakun ni Owode onirin, to si maa n ba wọn ja irin, o maa n sisẹ kara, kii se eeyan buruku, ko si kundun obinrin. Obinrin mẹrin lo wa nile bii ọmọ ọdọ mi, ko le dẹnu kọ ikankan wọn amọ oju aanu lo fẹ pa Lawal, yoo si dara ki Fola sọ iru eeyan ti lawal jẹ." Lizzy wa n gba Fola nimọran pe ko ye na owo lori ayẹyẹ to maa n lọ, nitori ibẹ gan lo n na owo le lori. Lizzy wa n kesi gbogbo awọn eeyan to n sepe fun lori ayelujara pe ayafi ti wọn ba le se ohun ti oun se fun obinrin naa ni erongba wọ̀n ko ni pada da le wọn lori. Lizzy Anjorin wa sisọ loju rẹ pe oun ti fi silẹ ninu akọsilẹ ogun oun pe gbogbo ọmọ ti ọkọ oun ba bi ati ti tiẹ naa, ni wọn maa pin ninu ogun oun. O ni orukọ awọn ọmọ Fola wa ninu iwe akọsilẹ ogun naa, ati pe ni aduru gbogbo ọmọ ti oun kọ orukọ wọn silẹ lati pin ogun oun, ẹyọ kan soso pere ni ti oun. O ni eyi fihan pe anfaani ti oun ba ni lati lọ silẹ okeere, ni awọn ọmọ obinrin naa ni pẹlu. "Emi n sisẹ, amọ Fola n gba owo lati maa lọ si pati. | Lizzy Anjorin: Èmi ń ṣiṣẹ́, obìnrin yìí ń gba owó láti fi ṣe àríyá Iroyin nipa osere tiata ati onisowo nni, Lizzy Anjorin ati ọkọ rẹ lo tun n rugbo ni ori ayelujara lọwọ lọwọ bayii. Eyi ko si sẹyin bi obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Fola Tinubu se n pariwo Lizzy ati ọkọ rẹ, Alhaji Lawal lori ayelujara. Fola lo kede fawọn akọroyin lori ayelujara pe iya n jẹ oun, ti oun ko si nile lori nitori bi Lizzy Anjorin se gba ọkọ oun, to si bimọ fun. Bakan naa lo fun wọn ni ohun to gba silẹ nipa itakurọsọ lori foonu laarin ohun ati Alhaji Lawal yii, nibi to ti n beere pe ki onitọun fi owo ransẹ si oun. Eyi lo mu ki Lizzy wa se fidio kan soju opo Instagram rẹ, to fi n fun obinrin naa lesi pe oun ko ni orogun rara, nitori oun nikan ni iyawo ti ọkọ oun fẹ. Nigba to n sọrọ lori bi obinrin ọlọmọ mẹta naa se ni iya n jẹ oun, Lizzy wa se afihan bi obinrin naa se gba owo to le ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira laarin osu Januari nikan. "Fola, o kan bimọ fun ọkọ mi ni, o kii se iyawo rẹ rara nitori ko ba ọ se igbeyawo tabi so yigi fun ọ. Laarin osu kinni ọdun si akoko yii, owo to ti gba lọwọ ọkọ mi to miliọnu kan naira, to si tun lọ ba baba onile rẹ pe ko parọ pe o ko tii sanwo ile. Ti mo ba jẹ eeyan buruku ni, n ko ni jẹ ki ọkọ mi fun ọ ni owo tabi Jeep Exterra ti mo ni ki ọkọ mi gbe fun ọ, bẹẹ ni emi ni mo jẹ ki ọkọ mi gba oyun nigba to loyun." Bakan naa tun ni Lizzy se afihan agbasilẹ fọnran ohun itakurọsọ laarin ọkọ rẹ, Lawal ati Baba Onile naa, ti onitsun si n salaye pe obinrin naa lo ni ki oun parọ pe ko tii sanwo ile. Bakan naa ni Lizzy tako obinrin naa peirọ nla ni aworan to n gbe kiri pe oun se igbeyawo pẹlu ọkọ oun, nitori aworan naa ni wọn ya nigba ti wọn n fi obinrin naa joye. Lizzy wa n sọ fun obinrin naa pe to ba jẹ pe bi oun se ranti rẹ, naa lo jẹ ki Lawal ranti awọn eeyan to saaju tiẹ naa ni, ko ba ri wọn pe loni. O fikun pe kii kuku se pe Fola yii nilo owo amọ o mọọmọ se fọnran ohun naa sita lati wọ oun nilẹ ni, ti Ọlọrun yoo si gbe oun leke gbogbo wọn. Wayi o, Lizzy Anjorin ti sọ fun obinrin ti wọn dijọ n fa surutu naa pe fọọmu fun ayẹwo DNA ti wa nilẹ fun, to si se afihan awọn fọọmu naa. "Ọmọ mẹta lo sọ fun araye pe o bi fun wa, agbẹjọro yoo pe ọ ni ọjọbọ ọla, to ba lọ se DNA naa, ko to kuro nibẹ, maa fi owo ransẹ si ọ, ko lọ se tara rẹ naa, ko ma baa da bii magomago. To ba jẹ Lawal lo ni ọmọ mẹtẹẹta, a yanju rẹ amọ to ba jẹ ẹyọ kan tabi meji ni ti Lawal nibẹ, a maa ja." Nigba to n fesi lori bi awọn eeyan se n yọ suti ete si ọkọ rẹ pe owo osere tiata naa lo n na lai ni isẹ kan pato lọwọ, lizzy salaye pe okoowo jọ pa oun ati ọkọ oun pọ ni. "Lawal kii se Jigolo, ibudo to ti n ta mọto mẹta lo ni laarin Lekki si Ajah, to si tun ni ileesẹ ti wọn ti n fọ ọkọ. Lawal n sisẹ takuntakun ni Owode onirin, to si maa n ba wọn ja irin, o maa n sisẹ kara, kii se eeyan buruku, ko si kundun obinrin. Obinrin mẹrin lo wa nile bii ọmọ ọdọ mi, ko le dẹnu kọ ikankan wọn amọ oju aanu lo fẹ pa Lawal, yoo si dara ki Fola sọ iru eeyan ti lawal jẹ." Lizzy wa n gba Fola nimọran pe ko ye na owo lori ayẹyẹ to maa n lọ, nitori ibẹ gan lo n na owo le lori. Lizzy wa n kesi gbogbo awọn eeyan to n sepe fun lori ayelujara pe ayafi ti wọn ba le se ohun ti oun se fun obinrin naa ni erongba wọ̀n ko ni pada da le wọn lori. Lizzy Anjorin wa sisọ loju rẹ pe oun ti fi silẹ ninu akọsilẹ ogun oun pe gbogbo ọmọ ti ọkọ oun ba bi ati ti tiẹ naa, ni wọn maa pin ninu ogun oun. O ni orukọ awọn ọmọ Fola wa ninu iwe akọsilẹ ogun naa, ati pe ni aduru gbogbo ọmọ ti oun kọ orukọ wọn silẹ lati pin ogun oun, ẹyọ kan soso pere ni ti oun. O ni eyi fihan pe anfaani ti oun ba ni lati lọ silẹ okeere, ni awọn ọmọ obinrin naa ni pẹlu. "Emi n sisẹ, amọ Fola n gba owo lati maa lọ si pati. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57171911 |
4religion
| Church founders allegedly kill member in fellowship: Bí olùdásílẹ̀ ìjọ méjì ṣe sin òkú ọmọ ìjọ láì sọ f'Ọ́lọ́pàá | Àwọn olùdásílẹ̀ ìjọ tó ṣekúpa ọmọ ìjọ àtàwọn afurasí míì kó sí gbaga ọlọ́pàá l'Ogun Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi oju afurasi ọdaran marundinlogun lede lori oniruru ẹsun bii idigunjale, ipaniyan, ijinigbe atawọn ẹsun mii. Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankole to fi oju awọn afurasi naa lede ni Eleweran, niluu Abeokuta sọ pe ọwọ awọn tẹ awọn afurasi naa kaakiri ipinlẹ ọhun. O ni awọn oṣiṣẹ oun mu awọn afurasi marundinlogun pẹlu oniruru ohun ija oloro lọwọ wọn. Olúwa mi, kò tọ́ ká bẹ ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ wò lára baba; Ẹ ṣọ́ra fún ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn lórí ayelujára o!- Agbẹjọ́rò Ramon Adedoyin Bankole ni awọn mu afurasi kan to pa okunrin kan to jẹ Fulani, to si sin oku rẹ sinu oko rẹ niluu Ewekoro. O ni awọn ti wu oku naa, awọn si ti gbe lọ si ile igbokupamọsi to wa niluu Ifo fun ayẹwo ati iwadii. Kọmiṣọna naa tẹsiwaju pe "Nigba ti o ta siwa leti pe okunrin kan, Saheed Ogudahun to jẹ ọdẹ, lọwọ ninu ipaniyan naa, ni a lọ fi ṣikun ofin mu." "Ninu ifọrọwanilẹnuwo ni agọ wa, o jẹwọ pe lootọ ni oun dana ibọn ya oloogbe naa ti oun si sin oku rẹ sinu igbo." Gómìnà Oyetola rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn aráàlù atí Oníṣẹ̀ṣe tó fẹ̀hónúhàn ní OAU torí VC tuntun tí kìí ṣe ọmọ ìlú Mọ̀ nípa ìlànà tí wọ́n n gbà yan ọ̀gá àgbà Fásítì, VC ní Naijiria 'Ojú ara méjì ni mo ní, wọ́n sì bí i mọ́ mí ni' Kàyééfì! Àṣírí ìyá àti ọmọkùnrin rẹ̀ tó jí ọmọ ọlọ́mọ gbé fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó f'ọ́dún mẹ́ta tú l'Ekiti Ileeṣẹ ọlọpaa naa tun fi oju awọn ajinigbe meji lede, Sulaimon Mohammed ati Jato Bello, ti awọn mejeji jẹ ẹni ogoji ọdun. Bakan naa ni wọn fi oju awọ afurasi mii lede, Chidi Samuel ati Paul Zakari, ti wọn jẹ oludasilẹ ijọ Life Builders Network, lori ẹsun pe wọn ṣekupa ọmọ ijọ wọn, Favour Okumazor, ni abule Oyan, to wa ni Imala, ni iha Ariwa Abeokuta. Bankole ni awọn afurasi naa ko awọn ọjẹ wẹwẹ kan bii meje kuro ni akata awọn wọn lọ fun ẹkọ Bibeli lọna ati ji wọn gbe lọ. Amọ aṣiri wọn tu lẹyin ti ọkan lara awọn ọmọ naa ke gbajare lọ ba awọn obi rẹ. Amọ ni igbẹyingbẹyin, akara wọn tu sepo, gbogbo si ti wa ni akata awọn ọlọpaa bayii ti wọn yoo si boju bale ẹjọ lẹyin iwadii. Taliban yí ìpinnu padà lórí fífi ààyè gba akẹ́kọ́ọ̀bìnrin láti padà sí kíláàsì Iná ńlá sọ ní ọ̀jà abẹ́ afárá Apongbon l'Eko Kí ló lè mú kí ìyá da bẹntiró sí ará ọmọ ọdún mẹ́wàá tó sì dáná sun ún? | Church founders allegedly kill member in fellowship: Bí olùdásílẹ̀ ìjọ méjì ṣe sin òkú ọmọ ìjọ láì sọ f'Ọ́lọ́pàá Àwọn olùdásílẹ̀ ìjọ tó ṣekúpa ọmọ ìjọ àtàwọn afurasí míì kó sí gbaga ọlọ́pàá l'Ogun Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi oju afurasi ọdaran marundinlogun lede lori oniruru ẹsun bii idigunjale, ipaniyan, ijinigbe atawọn ẹsun mii. Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankole to fi oju awọn afurasi naa lede ni Eleweran, niluu Abeokuta sọ pe ọwọ awọn tẹ awọn afurasi naa kaakiri ipinlẹ ọhun. O ni awọn oṣiṣẹ oun mu awọn afurasi marundinlogun pẹlu oniruru ohun ija oloro lọwọ wọn. Olúwa mi, kò tọ́ ká bẹ ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ wò lára baba; Ẹ ṣọ́ra fún ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn lórí ayelujára o!- Agbẹjọ́rò Ramon Adedoyin Bankole ni awọn mu afurasi kan to pa okunrin kan to jẹ Fulani, to si sin oku rẹ sinu oko rẹ niluu Ewekoro. O ni awọn ti wu oku naa, awọn si ti gbe lọ si ile igbokupamọsi to wa niluu Ifo fun ayẹwo ati iwadii. Kọmiṣọna naa tẹsiwaju pe "Nigba ti o ta siwa leti pe okunrin kan, Saheed Ogudahun to jẹ ọdẹ, lọwọ ninu ipaniyan naa, ni a lọ fi ṣikun ofin mu." "Ninu ifọrọwanilẹnuwo ni agọ wa, o jẹwọ pe lootọ ni oun dana ibọn ya oloogbe naa ti oun si sin oku rẹ sinu igbo." Gómìnà Oyetola rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn aráàlù atí Oníṣẹ̀ṣe tó fẹ̀hónúhàn ní OAU torí VC tuntun tí kìí ṣe ọmọ ìlú Mọ̀ nípa ìlànà tí wọ́n n gbà yan ọ̀gá àgbà Fásítì, VC ní Naijiria 'Ojú ara méjì ni mo ní, wọ́n sì bí i mọ́ mí ni' Kàyééfì! Àṣírí ìyá àti ọmọkùnrin rẹ̀ tó jí ọmọ ọlọ́mọ gbé fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó f'ọ́dún mẹ́ta tú l'Ekiti Ileeṣẹ ọlọpaa naa tun fi oju awọn ajinigbe meji lede, Sulaimon Mohammed ati Jato Bello, ti awọn mejeji jẹ ẹni ogoji ọdun. Bakan naa ni wọn fi oju awọ afurasi mii lede, Chidi Samuel ati Paul Zakari, ti wọn jẹ oludasilẹ ijọ Life Builders Network, lori ẹsun pe wọn ṣekupa ọmọ ijọ wọn, Favour Okumazor, ni abule Oyan, to wa ni Imala, ni iha Ariwa Abeokuta. Bankole ni awọn afurasi naa ko awọn ọjẹ wẹwẹ kan bii meje kuro ni akata awọn wọn lọ fun ẹkọ Bibeli lọna ati ji wọn gbe lọ. Amọ aṣiri wọn tu lẹyin ti ọkan lara awọn ọmọ naa ke gbajare lọ ba awọn obi rẹ. Amọ ni igbẹyingbẹyin, akara wọn tu sepo, gbogbo si ti wa ni akata awọn ọlọpaa bayii ti wọn yoo si boju bale ẹjọ lẹyin iwadii. Taliban yí ìpinnu padà lórí fífi ààyè gba akẹ́kọ́ọ̀bìnrin láti padà sí kíláàsì Iná ńlá sọ ní ọ̀jà abẹ́ afárá Apongbon l'Eko Kí ló lè mú kí ìyá da bẹntiró sí ará ọmọ ọdún mẹ́wàá tó sì dáná sun ún? | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60857497 |
3politics
| Father Mbaka: Àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá ló yẹ kí Buhari kọ́ dípò ríra ohun ìjà olóró | Gbajugbaja oniwaasu nni, Fada Ejike Mbaka tun ti fi ikilọ ranṣẹ si aarẹ Buhari lori awọn ohun elo ija to n kojọ. Mbaka lasiko to n waasu ninu ijọ rẹ, Adoration Ministry ni ilu Enugu ni, o ṣe ni laanu pe ohun ija ti aarẹ Buhari n kojọ yii gan an ni yoo rẹyin orilẹede NaijIria. Ohun to gba aarẹ Buhari ni iyanju lati ṣe ni ki o kọ awọn ileeṣẹ nla nla ti yoo pese iṣẹ fun awọn eniyan. ''Aarẹ Buhari ti o ko ba ṣọra, awọn ohun ija ọkọ baluu ofurufu to n ra wọnyii ni wọn yoo lo lati fi doju orilẹede Naijiria bolẹ. ''Ẹ jọwọ ẹni akọkọ to ba ri aarẹ Buhari lẹyin iwaasu yii ni ko jiṣẹ fun un lori ọna iparun to wa ninu kikọ awọn dukia ijagun pamọ.'' ''Ọlọrun lo ni ki n sọ fun aarẹ Buhari bẹẹ ni asiko yii.'' ''O to gẹ lori ọrọ rira ohun ija ijagun, kọ kọ kọ awọn ileeṣẹ nla nla. Amọ ni ọsẹ to kọja lasiko ti aarẹ Buhari sọrọ lo ni pe awon ti n ko awon ohun ijagun tuntun miran wọ orilẹede Naijiria lati awọn orilẹede to fẹran wa. Buhari ni awọn ohun ijagun naa ni wọn yoo fi koju eto aabo to dẹnukọlẹ kaakiri orilẹede Naijiria. ''Awọn ohun ija yii yoo ran wa lọwọ lati tete bori eto aabo to dẹnukọlẹ.'' Ẹgbẹ awọn alagbata gaasi idana ti n kọminu lori bi wọn ko ṣe ri ọja ta, eyii to mu ki gaasi ọhun ma fi ojojumọ gbowo lori ni Naijiria. Akọwe agba ẹgbẹ naa, Bassey Essien sọ nibi ipade ita gbangba kan ti ẹgbẹ naa ṣe pe o ṣeeṣe ki iye owo ti awọn araalu n ra gaasi naa di ẹgbẹrun mẹwaa ko ti do oṣu kejila ọdun yii. Iwọn gaasi 12.5kg ti awọn eeyan n ra ni ẹgbẹrun mẹrin ibẹrẹ yii ti di nnkan bii ẹgbẹrun meje si mẹjọ bayii. Awọn alagbata gaasi naa ni pupọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n lo eedu ati ina igi nitori ọwọngogo gaasi. Essien ni ijọba apapọ gbọdọ ṣe atunyẹwo awọn owo ori to n gba lori awọn ọja ti wọn n ko wọ Naijiria lati ilẹ okeere ati iye owo ori VAT. O ni bi bẹẹ kọ, o ṣeeṣe ki awọn maa ta iwọn gaasi 12.5kg ni ẹgbẹrun mẹwaa naira. O ni "Lonii yii, iye owo gaasi ti di ₦7,500 si ₦8,000, ṣugbọn awọn n gbiyanju ki owo naa ma baa wọn ju bẹẹ lọ." "Fun apẹrẹ, iye ti a n ra ogun tọọnu gaasi ko to miliọnu marun un naira lọdun to kọja, ṣugbọn bayii o ti le miliọnu mẹwaa naira." "Niwọn igba ti a ko ba ri ọja ra, iye ti a n taa fun awọn araalu gbọdọ gbowo lori dandan ni." Nigba to sọrọ lori bi awọn alagbata ko ṣe ta daadaa bii ti atẹyinwa, o ni pupọ ọmọ Naijiria lo ti pada si lilo epo kẹrosini, sawdust, igi idana ati bẹẹ bẹẹ lọ. Gẹgẹ bii ohun to sọ, ẹgbẹ naa ti n ba ijọba jiroro lori ọna abayọ si iṣoro ọwọngogo gaasi ọhun laarin awọn to n ko wọ Naijiria lati oke okun ati awọn alagbata. Ẹgbẹ naa pari ọrọ wọn pe yatọ si gaasi, silinda ti wọn rọ gaasi naa si tun ti gbowo lori ju ti tẹlẹ lọ nitori oke okun ni wọn ti n ko awọn eroja ti wọn fi n ṣe silinda ọhun wọ Naijria. | Father Mbaka: Àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá ló yẹ kí Buhari kọ́ dípò ríra ohun ìjà olóró Gbajugbaja oniwaasu nni, Fada Ejike Mbaka tun ti fi ikilọ ranṣẹ si aarẹ Buhari lori awọn ohun elo ija to n kojọ. Mbaka lasiko to n waasu ninu ijọ rẹ, Adoration Ministry ni ilu Enugu ni, o ṣe ni laanu pe ohun ija ti aarẹ Buhari n kojọ yii gan an ni yoo rẹyin orilẹede NaijIria. Ohun to gba aarẹ Buhari ni iyanju lati ṣe ni ki o kọ awọn ileeṣẹ nla nla ti yoo pese iṣẹ fun awọn eniyan. ''Aarẹ Buhari ti o ko ba ṣọra, awọn ohun ija ọkọ baluu ofurufu to n ra wọnyii ni wọn yoo lo lati fi doju orilẹede Naijiria bolẹ. ''Ẹ jọwọ ẹni akọkọ to ba ri aarẹ Buhari lẹyin iwaasu yii ni ko jiṣẹ fun un lori ọna iparun to wa ninu kikọ awọn dukia ijagun pamọ.'' ''Ọlọrun lo ni ki n sọ fun aarẹ Buhari bẹẹ ni asiko yii.'' ''O to gẹ lori ọrọ rira ohun ija ijagun, kọ kọ kọ awọn ileeṣẹ nla nla. Amọ ni ọsẹ to kọja lasiko ti aarẹ Buhari sọrọ lo ni pe awon ti n ko awon ohun ijagun tuntun miran wọ orilẹede Naijiria lati awọn orilẹede to fẹran wa. Buhari ni awọn ohun ijagun naa ni wọn yoo fi koju eto aabo to dẹnukọlẹ kaakiri orilẹede Naijiria. ''Awọn ohun ija yii yoo ran wa lọwọ lati tete bori eto aabo to dẹnukọlẹ.'' Ẹgbẹ awọn alagbata gaasi idana ti n kọminu lori bi wọn ko ṣe ri ọja ta, eyii to mu ki gaasi ọhun ma fi ojojumọ gbowo lori ni Naijiria. Akọwe agba ẹgbẹ naa, Bassey Essien sọ nibi ipade ita gbangba kan ti ẹgbẹ naa ṣe pe o ṣeeṣe ki iye owo ti awọn araalu n ra gaasi naa di ẹgbẹrun mẹwaa ko ti do oṣu kejila ọdun yii. Iwọn gaasi 12.5kg ti awọn eeyan n ra ni ẹgbẹrun mẹrin ibẹrẹ yii ti di nnkan bii ẹgbẹrun meje si mẹjọ bayii. Awọn alagbata gaasi naa ni pupọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n lo eedu ati ina igi nitori ọwọngogo gaasi. Essien ni ijọba apapọ gbọdọ ṣe atunyẹwo awọn owo ori to n gba lori awọn ọja ti wọn n ko wọ Naijiria lati ilẹ okeere ati iye owo ori VAT. O ni bi bẹẹ kọ, o ṣeeṣe ki awọn maa ta iwọn gaasi 12.5kg ni ẹgbẹrun mẹwaa naira. O ni "Lonii yii, iye owo gaasi ti di ₦7,500 si ₦8,000, ṣugbọn awọn n gbiyanju ki owo naa ma baa wọn ju bẹẹ lọ." "Fun apẹrẹ, iye ti a n ra ogun tọọnu gaasi ko to miliọnu marun un naira lọdun to kọja, ṣugbọn bayii o ti le miliọnu mẹwaa naira." "Niwọn igba ti a ko ba ri ọja ra, iye ti a n taa fun awọn araalu gbọdọ gbowo lori dandan ni." Nigba to sọrọ lori bi awọn alagbata ko ṣe ta daadaa bii ti atẹyinwa, o ni pupọ ọmọ Naijiria lo ti pada si lilo epo kẹrosini, sawdust, igi idana ati bẹẹ bẹẹ lọ. Gẹgẹ bii ohun to sọ, ẹgbẹ naa ti n ba ijọba jiroro lori ọna abayọ si iṣoro ọwọngogo gaasi ọhun laarin awọn to n ko wọ Naijiria lati oke okun ati awọn alagbata. Ẹgbẹ naa pari ọrọ wọn pe yatọ si gaasi, silinda ti wọn rọ gaasi naa si tun ti gbowo lori ju ti tẹlẹ lọ nitori oke okun ni wọn ti n ko awọn eroja ti wọn fi n ṣe silinda ọhun wọ Naijria. | https://www.bbc.com/yoruba/media-58861428 |
4religion
| TB Joshua: Apostle Paul M.E ti kéde ikú àgbà wòlíì náà láti oṣù kan sẹ́yìn | Gẹgẹ bi awọn alasẹ ijọ Synagogue Church of All Nations (SCOAN) se sọ lasiko ti wọn n kede iku oludasilẹ ijọ naa, Wolii TB Joshua, bẹẹ ni ọrọ iku rẹ ri. Ijọ naa lo kede ni owurọ ọjọ Aiku pe Ọlọrun kii se nnkan, ko ma kọkọ fi han awọn wolii rẹ saaju. Bakan naa ni ọrọ ri pẹlu Wolii kan, to ti kọkọ sọ asọtẹlẹ ni osu kan sẹyin pe Ọlarun ti setan lati mu Wolii Temitope Balogun Joshua lọ sile ayeraye. Ninu fidio kan to gba awọn oju opo ayelujara kan, ni ojisẹ Ọlọrun kan Apostle M.E Paul ti n sasọtẹlẹ pe oun ri awọn angẹli, ti wọn wa gbe wolii TB Joshua lọ kuro laye. "Ọlọrun fi iran igba ikẹyin kan han mi, ẹ tẹti si mi, mo duro silẹ, a si gbe mi lọ si ọrun, ferese ọrun si silẹ fun mi, mo si duro lati boju wo isalẹ ilẹ nile aye. Mo ri awọn angẹli mẹfa ti a ran lati ọrun wa sile aye pe ki wọn lọ gbe wolii Joshua wa, ohun ti mo ri ni mo n sọ. Awọn angẹli mẹta mu dani ni ọwọ ọtun ati mẹta ni ọwọ osi, ti wọn gbe wolii TB Joshua soke tente, to si mu ife ẹyẹ kan dani." Wolii Paul ni oun wo ibi ti awọn wolii naa duro si, ti wọn si ya si apa ọtun, oun naa ba woju wo apa ọtun, amọ oun ko ri oju ẹni to joko sori itẹ. Bakan naa ni Apostle M.E Paul ni oun gbọ ohun Ọlọrun to n sọ fawọn angẹli naa pe ki wọn gba ife ẹyẹ naa lọwọ Wolii Joshua, ki wọn si mu wa fun oun. Bakan naa lo ni ki wọn mu wolii naa lọ sibi to yẹ fun. "Lọgan ni mo ri awọn agba angẹli to tun ju awọn ti isaaju lọ, ti wọn n duro sẹba itẹ Ọlọrun, wsn wa gba ife ẹyẹ naa lọwọ wolii TB Joshua, ti wọn si gbe lọ siwaju itẹ Ọlọrun. O ni Oluwa ni ki awọn angẹli yii si gbe wolii si ibi to yẹ ko wa nitori o ti pari ire ije rẹ nile aye. | TB Joshua: Apostle Paul M.E ti kéde ikú àgbà wòlíì náà láti oṣù kan sẹ́yìn Gẹgẹ bi awọn alasẹ ijọ Synagogue Church of All Nations (SCOAN) se sọ lasiko ti wọn n kede iku oludasilẹ ijọ naa, Wolii TB Joshua, bẹẹ ni ọrọ iku rẹ ri. Ijọ naa lo kede ni owurọ ọjọ Aiku pe Ọlọrun kii se nnkan, ko ma kọkọ fi han awọn wolii rẹ saaju. Bakan naa ni ọrọ ri pẹlu Wolii kan, to ti kọkọ sọ asọtẹlẹ ni osu kan sẹyin pe Ọlarun ti setan lati mu Wolii Temitope Balogun Joshua lọ sile ayeraye. Ninu fidio kan to gba awọn oju opo ayelujara kan, ni ojisẹ Ọlọrun kan Apostle M.E Paul ti n sasọtẹlẹ pe oun ri awọn angẹli, ti wọn wa gbe wolii TB Joshua lọ kuro laye. "Ọlọrun fi iran igba ikẹyin kan han mi, ẹ tẹti si mi, mo duro silẹ, a si gbe mi lọ si ọrun, ferese ọrun si silẹ fun mi, mo si duro lati boju wo isalẹ ilẹ nile aye. Mo ri awọn angẹli mẹfa ti a ran lati ọrun wa sile aye pe ki wọn lọ gbe wolii Joshua wa, ohun ti mo ri ni mo n sọ. Awọn angẹli mẹta mu dani ni ọwọ ọtun ati mẹta ni ọwọ osi, ti wọn gbe wolii TB Joshua soke tente, to si mu ife ẹyẹ kan dani." Wolii Paul ni oun wo ibi ti awọn wolii naa duro si, ti wọn si ya si apa ọtun, oun naa ba woju wo apa ọtun, amọ oun ko ri oju ẹni to joko sori itẹ. Bakan naa ni Apostle M.E Paul ni oun gbọ ohun Ọlọrun to n sọ fawọn angẹli naa pe ki wọn gba ife ẹyẹ naa lọwọ Wolii Joshua, ki wọn si mu wa fun oun. Bakan naa lo ni ki wọn mu wolii naa lọ sibi to yẹ fun. "Lọgan ni mo ri awọn agba angẹli to tun ju awọn ti isaaju lọ, ti wọn n duro sẹba itẹ Ọlọrun, wsn wa gba ife ẹyẹ naa lọwọ wolii TB Joshua, ti wọn si gbe lọ siwaju itẹ Ọlọrun. O ni Oluwa ni ki awọn angẹli yii si gbe wolii si ibi to yẹ ko wa nitori o ti pari ire ije rẹ nile aye. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57385528 |
2health
| Port Harcourt Sextuplet: Joyce ní ọjọ́ tí òun bímọ lòun mọ̀ pé oyún ìbẹfà ló wà nínú òun | Ẹ ku ọwọ lomi lo yẹ ki a maa ki tọkọ-taya Joyce ati Bright Akhimien ti Eledua ti fi odindi ọmọ mẹfa ta lọrẹ lẹẹkan ṣoso. Lẹyin ọdun meje ti Joyce, ẹni ọdun mọkandinlogoji ati ọkọ rẹ, DSP Bright Akhimien ti wọn wa lati ipinlẹ Edo ni Olodumare to da wọn lohun. Ọkunrin mẹrin ati obinrin meji lawọn ọmọ naa ti wọn bi lọjọ kejila, oṣu kinni, ọdun 2021 niluu Port Harcourt nipinlẹ Rivers. Joyce ni oun ko mọ pe ọmọ mẹfa loun yoo bi lẹẹkan naa lẹyin ti dokita sọ fun oun pe ọmọ to pọ lo wa ninu oun. O ni: ''Ọjọ ti mo bi awọn ọmọ naa lawọn nọọsi bẹrẹ si ni ka wọn ti wọn si ri i pe mẹfa lawọn ọmọ naa,'' Joyce ṣalaye. ''O ṣoro fun mi lati mọ iye ọmọ to wa ninu mi nigba naa tori nigba kuu gba ti a ba lọ si ayẹwo ni awọn ọmọ naa maa n bo ara wọn mọlẹ. Eleyi to maa n jẹ ko nira lati mọ iye ọmọ to wa ninu mi,'' Joyce lo sọ bẹẹ. Joyce ṣalaye pe inu oun dun debi pe oun ko mọ ohun ti oun tiẹ le sọ gan an. O ni ''iyalẹnu lo jẹ fun mi bi Eleduwa ṣe n ṣiṣẹ rẹ pẹlu ọmọ mẹfa ti Ọba oke fi jinki emi ati idile mi.'' Bo tilẹ jẹ pe wọn padanu ọkan lara awọn obinrin to wa ninu awọn naa, wọn si n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ẹbun pataki yii. ''Niṣe ni mo n bi ara mi leere pe ṣe emi naa ree, lẹyin gbogbo ohun ti oju mi ti ri fun ọdun meje. Emi naa ni mo wa di ẹni to n ka ọmọ ni meni meji, omije ayọ lo n jabọ loju mi bi mo ti n yin Ọlọrun pe O ranti mi,'' Joyce lo sọ fawọn akọroyin bẹẹ. Ọjọ kọkanla, oṣu kinni, ọdun 2014 ni Joyce ati Bright ṣe igbeyawo ti wọn si gbadura fun ere idi igbeyawo. Ojoojumọ ni mo n yin Olorun logo nibi to sin mi de. Lẹyin ọdun kan ti wọn ṣe igbeyawo ni Joyce bi ọmọkunrin kan, ṣugbọn lẹyin ọjọ kan ti ọmọ naa de ile aye lo pada. Joyce ni lati igba naa, oun ko loyun lati aarọ di alẹ ri, bẹẹ ni oun ko loyun ki oyun naa wa bajẹ. O ni ọkọ oun gbaruku ti oun lasiko tawọn fi n wo oju Ọlọrun, ṣugbọn awọn ẹbi lo beere ni gbogbo igba. ''Ọjọ kan wa ti mo lọ ki ẹnikan to bimọ ni abule, nibi ti mo ti fẹ gbe ọmọ ni iya rẹ kọ fun mi lati gbe e, o dun mi gan na, koda mo sunkun nigba ti mo dele. Arabinrin Akhimien ṣalaye pe alakọkọ ti oun ṣe eto ati loyun pẹlu ilana IVF naa ni oun bimọ yii. ''Niṣe ni a wa owo lati ṣe IVF nitori owo rẹ pọ gan an, ṣugbọn Ọlọrun gbọ adura wa, ẹkan ti a ṣe naa ni a si bimọ. Bright, baba ibẹfa naa sọ fawọn akọroyin pe oun ko tiẹ fi ọkan si nigba ti iyawo oun sọ pe oun ti loyun nitori oun ko fẹ nkan to maa ba oun ninu jẹ. ''Oṣu kinni kọja, oṣu keji, nigba ti o di oṣu kẹta ni a bẹrẹ si ni gbagbọ pe Ọlọrun ti da wa lohun,'' Bright ṣalaye. O dupẹ lọwọ Eleduwa pe O ranti awọn fun ni ẹbun pataki ọmọ mẹfa lẹẹkan ṣoṣo. | Port Harcourt Sextuplet: Joyce ní ọjọ́ tí òun bímọ lòun mọ̀ pé oyún ìbẹfà ló wà nínú òun Ẹ ku ọwọ lomi lo yẹ ki a maa ki tọkọ-taya Joyce ati Bright Akhimien ti Eledua ti fi odindi ọmọ mẹfa ta lọrẹ lẹẹkan ṣoso. Lẹyin ọdun meje ti Joyce, ẹni ọdun mọkandinlogoji ati ọkọ rẹ, DSP Bright Akhimien ti wọn wa lati ipinlẹ Edo ni Olodumare to da wọn lohun. Ọkunrin mẹrin ati obinrin meji lawọn ọmọ naa ti wọn bi lọjọ kejila, oṣu kinni, ọdun 2021 niluu Port Harcourt nipinlẹ Rivers. Joyce ni oun ko mọ pe ọmọ mẹfa loun yoo bi lẹẹkan naa lẹyin ti dokita sọ fun oun pe ọmọ to pọ lo wa ninu oun. O ni: ''Ọjọ ti mo bi awọn ọmọ naa lawọn nọọsi bẹrẹ si ni ka wọn ti wọn si ri i pe mẹfa lawọn ọmọ naa,'' Joyce ṣalaye. ''O ṣoro fun mi lati mọ iye ọmọ to wa ninu mi nigba naa tori nigba kuu gba ti a ba lọ si ayẹwo ni awọn ọmọ naa maa n bo ara wọn mọlẹ. Eleyi to maa n jẹ ko nira lati mọ iye ọmọ to wa ninu mi,'' Joyce lo sọ bẹẹ. Joyce ṣalaye pe inu oun dun debi pe oun ko mọ ohun ti oun tiẹ le sọ gan an. O ni ''iyalẹnu lo jẹ fun mi bi Eleduwa ṣe n ṣiṣẹ rẹ pẹlu ọmọ mẹfa ti Ọba oke fi jinki emi ati idile mi.'' Bo tilẹ jẹ pe wọn padanu ọkan lara awọn obinrin to wa ninu awọn naa, wọn si n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ẹbun pataki yii. ''Niṣe ni mo n bi ara mi leere pe ṣe emi naa ree, lẹyin gbogbo ohun ti oju mi ti ri fun ọdun meje. Emi naa ni mo wa di ẹni to n ka ọmọ ni meni meji, omije ayọ lo n jabọ loju mi bi mo ti n yin Ọlọrun pe O ranti mi,'' Joyce lo sọ fawọn akọroyin bẹẹ. Ọjọ kọkanla, oṣu kinni, ọdun 2014 ni Joyce ati Bright ṣe igbeyawo ti wọn si gbadura fun ere idi igbeyawo. Ojoojumọ ni mo n yin Olorun logo nibi to sin mi de. Lẹyin ọdun kan ti wọn ṣe igbeyawo ni Joyce bi ọmọkunrin kan, ṣugbọn lẹyin ọjọ kan ti ọmọ naa de ile aye lo pada. Joyce ni lati igba naa, oun ko loyun lati aarọ di alẹ ri, bẹẹ ni oun ko loyun ki oyun naa wa bajẹ. O ni ọkọ oun gbaruku ti oun lasiko tawọn fi n wo oju Ọlọrun, ṣugbọn awọn ẹbi lo beere ni gbogbo igba. ''Ọjọ kan wa ti mo lọ ki ẹnikan to bimọ ni abule, nibi ti mo ti fẹ gbe ọmọ ni iya rẹ kọ fun mi lati gbe e, o dun mi gan na, koda mo sunkun nigba ti mo dele. Arabinrin Akhimien ṣalaye pe alakọkọ ti oun ṣe eto ati loyun pẹlu ilana IVF naa ni oun bimọ yii. ''Niṣe ni a wa owo lati ṣe IVF nitori owo rẹ pọ gan an, ṣugbọn Ọlọrun gbọ adura wa, ẹkan ti a ṣe naa ni a si bimọ. Bright, baba ibẹfa naa sọ fawọn akọroyin pe oun ko tiẹ fi ọkan si nigba ti iyawo oun sọ pe oun ti loyun nitori oun ko fẹ nkan to maa ba oun ninu jẹ. ''Oṣu kinni kọja, oṣu keji, nigba ti o di oṣu kẹta ni a bẹrẹ si ni gbagbọ pe Ọlọrun ti da wa lohun,'' Bright ṣalaye. O dupẹ lọwọ Eleduwa pe O ranti awọn fun ni ẹbun pataki ọmọ mẹfa lẹẹkan ṣoṣo. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-55951659 |
3politics
| Bola Tinubu: APC Eko ní Tinubu ló sọ Bode George di èèyàn lágbo òsèlú àmọ́ ògo rẹ̀ ti ń lọ sílẹ̀ | Sáájú ìdìbò ọdún 2023 ní Nàíjírà àti ìpinu Asíwáju Bola Ahmed Tinubu láti di ààrẹ, oníruurú ọ̀rọ̀ ló n tàn ka lórílẹ̀-èdè Naàìjíríà. Lára rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ti ìgbákejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) tẹ́lẹ̀ rí, Olabode George sọ pé, Ahmed Tinubu ko yẹ lẹni ti ó yẹ kí ó jẹ ààrẹ lọ́dún 2023. Bode George fi kun pé, gbogbo ẹni to bá sì rò pé Tinubu ló tọ́ sí láti di ààrẹ, irú ẹni bẹ́ẹ̀ nílò àyẹ̀wò nílé ìwòsàn. Bákan náà ló sọ pé láàrín ọdún mẹ́jọ tí Tinubu fi jẹ gómínà ìpínlẹ̀ Eko gbogbo àlùmọ́nì ìpínlẹ náà lo ṣe básubàsu. Èyí lo wá mú kí àwọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ nilẹ oruba ati èèkàn kan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress (APC) fi n sọ òkò ọ̀rọ̀ padà sí Olabode George. Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, alága ẹgbẹ́ Yorùbá Welfare Group (YWG) Alhaji Abdulkareem Adegoke Alawuje ṣàlàyé pé, ìjà ìlàra ni Bode George ń jà àti pé ìjà ìlàra kìí tán bọ̀rọ̀. Adegoke ni, gbogbo àwọn ìpìlẹ̀ tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Eko lónìí, Tinubu ló ṣe àgbékalẹ wọn, nítori náà, Bode George ko rì nǹkan sọ lórí pe Tinubu ṣe àlùmọ́nì ìpínlẹ̀ Eko básubàsù. "Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni Tinubu ko fi gba owó láti ọdọ̀ ìjọba àpapọ̀ síbẹ̀ , ètò ọ̀rọ̀ ajé Eko sì n ru gọbọi síí ni" Bola Ahmed Tinubu ni olórí tí gbogbo ọmọ ilẹ̀ káàrọ̀-òò-jííre nílò ni àsìkò yìí, kíló de ti Yorùbá náà ló tún fa ọmọ Yorùbá sẹ́yìn. Adegoke fi kún pé tí Bode George bá fẹ́ kúrò ní Nàìjíríà, kò ṣe nǹkankan fún ẹnikẹni nítorí kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, ẹrú ló rà wọ́n wá, orúkọ ẹru tó ra àwọn baba ńla bàbá rẹ̀ lo ń jẹ George. Ó ni kìí ṣe òní ni Bode George ti máa n sọ ọ̀rọ̀ yìí, kò sì ni turu kankan lára ẹnikẹni nítorí pé, agbegbe Ìjọrá ni wọn kó awọn iran rẹ to jẹ ẹru si lásìkò owò ẹrú, ó sì wà lára àwọn ti kò mọ orísun wọn mọ́. "Adegoke ní gẹ́gẹ́ bi ọmọ Nàìjíríà àti ọmọ Yorùbá, kò sí nǹkan tí ó le ṣẹ̀lẹ̀ ní Nàìjíríà, tí mo fi le ròó pé mọ̀ fẹ́ fi orílẹ̀-èdè mí sílẹ̀ "Gẹ́gẹ́ bi ẹni tó mọ pé wọ́n ra àwọn bàbá àwọn wá ni, kò ni niwọ́n lára láti padà sí ọ̀dọ́ àwọn tó rà wọ́n tàbi ibi ti wọ́n ti rà wọ́n kiri." "Àwá sì le júwe ibi ti wọ́n ti rà wọ́n pẹ̀lú agádagodo lẹnu wọ́n" Láti ìgbà tí Bode George tí n ṣe òṣèlú kò sí ẹni tó ri ipa ire kan ti o se nilẹ Yorùba, ní Eko tabi ni orílẹ̀-edè Nàìjíríà." " Ṣebí Bode George naa ti jẹ Gómìnà rí, kí lo ṣe lásìkò rẹ̀, kò sí ipa kankan ti wọ́n ni." Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, akọ̀wé ipòlongo fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Eko, Joe Igbokwe ṣàlàyé pé ìlàra ni kò jẹ́ kí Olabode George gbádun nítori pé o kàn ń ṣe inúnibini sí àṣeyọri Bola Ahmed Tinubu ni Nàìjíríà ni. Igbokwe to tẹpẹlẹ mọ pé, àṣeyọri Tinubu kò dúró ni ìpínlẹ̀ Eko nìkàn, bákan náà lo ni àwọn tó ti sọ di ènìyàn ńla láwùjọ, èyí ti òun gan jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ti Tinubu sọ di èyàn. Igbokwe ni o ti dandan tí ènìyàn bá jẹ ìlúmọ̀ọ̀ká, ọ̀pọ̀ ni yóò ma sọ̀rọ̀ rẹ̀, 'tí ènìyàn kan ba n lọ sókè, tí ẹlòmíràn si ń lọ sílẹ̀, ẹni tó n lọ sílẹ̀ yẹn yóò maa ba ẹni tó wà lóke jẹ́ ni. "Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Bode George ṣe rí, Bode George ti tán, ó sì ń wá ẹni kúnra nítorí ètò òṣèlú rẹ̀ ti tán." Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, agba ọjẹ kan ninu ẹgbẹ oselu PDP, Oloye Olabode George ti sọrọ soke lori erongba asaaju ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Tinubu lati du ipo aarẹ. George fi ero rẹ lori erongba Tinubu lati du ipo aarẹ han lasiko to n kopa lori eto ori tẹlifisan kan nileesẹ Arise TV lọjọru. Lero ti asaaju ẹgbẹ PDP naa, ara gbogbo awọn eeyan to n sugba Tinubu lati di aarẹ lọdun 2023 ni ara wọn ko ya, wọn si nilo ayẹwo ọpọlọ. Ọmọ igbimọ majẹobajẹ fẹgbẹ oselu PDP naa ni oun yoo kede pe oun kii se ọmọ Naijiria mọ, ti Tinubu ba fi di aarẹ Naijiria lọdun 2023. Bẹẹ ba gbagbe, asaaju ẹgbẹ oselu APC kan, Adeseye Ogunlewe lo ti kọkọ kede pe Tinubu ni oludije to dantọ julọ lati dari Naijiria lọdun 2023. Nigba to n fesi si ọrọ naa siwaju, George ni se ni oun bẹrẹ si ronu nigba ti oun gbọ ọrọ Ogunlewe naa nitori ọkunrin naa ti kọkọ sọrọ saaju lati tabuku Tinubu, to si wa ni akọsilẹ. "Ki lo de tawọn eeyan kii le duro lori ọrọ ti wọn ba sọ gan? Ki lo de ti wọn n jo bi eleegun kiri laarin ọja? Ta ba se agbeyẹwo ọdun mẹjọ ti Tinubu lo bii gomina nipinlẹ Eko, bawo la ti se idajọ rẹ si? Mo setan lati ba Ogunlewe se ariyanjiyan nipa Tinubu nibi kibi, koda, ko baa jẹ ni itẹ oku ni aago mẹta oru, ọrọkọrọ lo n sọ lẹnu. Koda, maa se ohun gbogbo to ba yẹ lati kede pe n ko kii se ọmọ orilẹede yi mọ ti Tinubu ba fi di aarẹ." Bode George, ẹni to ni ọmọ ipinlẹ Eko ni oun, oun si mọ awọn nnkan ti Tinubu se, wa fi ọwọ sọya pe ko yẹ bii aarẹ rara, ti awọn gomina miran to dari ipnilẹ Eko si kaato julọ. | Bola Tinubu: APC Eko ní Tinubu ló sọ Bode George di èèyàn lágbo òsèlú àmọ́ ògo rẹ̀ ti ń lọ sílẹ̀ Sáájú ìdìbò ọdún 2023 ní Nàíjírà àti ìpinu Asíwáju Bola Ahmed Tinubu láti di ààrẹ, oníruurú ọ̀rọ̀ ló n tàn ka lórílẹ̀-èdè Naàìjíríà. Lára rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ti ìgbákejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) tẹ́lẹ̀ rí, Olabode George sọ pé, Ahmed Tinubu ko yẹ lẹni ti ó yẹ kí ó jẹ ààrẹ lọ́dún 2023. Bode George fi kun pé, gbogbo ẹni to bá sì rò pé Tinubu ló tọ́ sí láti di ààrẹ, irú ẹni bẹ́ẹ̀ nílò àyẹ̀wò nílé ìwòsàn. Bákan náà ló sọ pé láàrín ọdún mẹ́jọ tí Tinubu fi jẹ gómínà ìpínlẹ̀ Eko gbogbo àlùmọ́nì ìpínlẹ náà lo ṣe básubàsu. Èyí lo wá mú kí àwọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ nilẹ oruba ati èèkàn kan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress (APC) fi n sọ òkò ọ̀rọ̀ padà sí Olabode George. Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, alága ẹgbẹ́ Yorùbá Welfare Group (YWG) Alhaji Abdulkareem Adegoke Alawuje ṣàlàyé pé, ìjà ìlàra ni Bode George ń jà àti pé ìjà ìlàra kìí tán bọ̀rọ̀. Adegoke ni, gbogbo àwọn ìpìlẹ̀ tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Eko lónìí, Tinubu ló ṣe àgbékalẹ wọn, nítori náà, Bode George ko rì nǹkan sọ lórí pe Tinubu ṣe àlùmọ́nì ìpínlẹ̀ Eko básubàsù. "Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni Tinubu ko fi gba owó láti ọdọ̀ ìjọba àpapọ̀ síbẹ̀ , ètò ọ̀rọ̀ ajé Eko sì n ru gọbọi síí ni" Bola Ahmed Tinubu ni olórí tí gbogbo ọmọ ilẹ̀ káàrọ̀-òò-jííre nílò ni àsìkò yìí, kíló de ti Yorùbá náà ló tún fa ọmọ Yorùbá sẹ́yìn. Adegoke fi kún pé tí Bode George bá fẹ́ kúrò ní Nàìjíríà, kò ṣe nǹkankan fún ẹnikẹni nítorí kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, ẹrú ló rà wọ́n wá, orúkọ ẹru tó ra àwọn baba ńla bàbá rẹ̀ lo ń jẹ George. Ó ni kìí ṣe òní ni Bode George ti máa n sọ ọ̀rọ̀ yìí, kò sì ni turu kankan lára ẹnikẹni nítorí pé, agbegbe Ìjọrá ni wọn kó awọn iran rẹ to jẹ ẹru si lásìkò owò ẹrú, ó sì wà lára àwọn ti kò mọ orísun wọn mọ́. "Adegoke ní gẹ́gẹ́ bi ọmọ Nàìjíríà àti ọmọ Yorùbá, kò sí nǹkan tí ó le ṣẹ̀lẹ̀ ní Nàìjíríà, tí mo fi le ròó pé mọ̀ fẹ́ fi orílẹ̀-èdè mí sílẹ̀ "Gẹ́gẹ́ bi ẹni tó mọ pé wọ́n ra àwọn bàbá àwọn wá ni, kò ni niwọ́n lára láti padà sí ọ̀dọ́ àwọn tó rà wọ́n tàbi ibi ti wọ́n ti rà wọ́n kiri." "Àwá sì le júwe ibi ti wọ́n ti rà wọ́n pẹ̀lú agádagodo lẹnu wọ́n" Láti ìgbà tí Bode George tí n ṣe òṣèlú kò sí ẹni tó ri ipa ire kan ti o se nilẹ Yorùba, ní Eko tabi ni orílẹ̀-edè Nàìjíríà." " Ṣebí Bode George naa ti jẹ Gómìnà rí, kí lo ṣe lásìkò rẹ̀, kò sí ipa kankan ti wọ́n ni." Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, akọ̀wé ipòlongo fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Eko, Joe Igbokwe ṣàlàyé pé ìlàra ni kò jẹ́ kí Olabode George gbádun nítori pé o kàn ń ṣe inúnibini sí àṣeyọri Bola Ahmed Tinubu ni Nàìjíríà ni. Igbokwe to tẹpẹlẹ mọ pé, àṣeyọri Tinubu kò dúró ni ìpínlẹ̀ Eko nìkàn, bákan náà lo ni àwọn tó ti sọ di ènìyàn ńla láwùjọ, èyí ti òun gan jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ti Tinubu sọ di èyàn. Igbokwe ni o ti dandan tí ènìyàn bá jẹ ìlúmọ̀ọ̀ká, ọ̀pọ̀ ni yóò ma sọ̀rọ̀ rẹ̀, 'tí ènìyàn kan ba n lọ sókè, tí ẹlòmíràn si ń lọ sílẹ̀, ẹni tó n lọ sílẹ̀ yẹn yóò maa ba ẹni tó wà lóke jẹ́ ni. "Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Bode George ṣe rí, Bode George ti tán, ó sì ń wá ẹni kúnra nítorí ètò òṣèlú rẹ̀ ti tán." Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, agba ọjẹ kan ninu ẹgbẹ oselu PDP, Oloye Olabode George ti sọrọ soke lori erongba asaaju ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Tinubu lati du ipo aarẹ. George fi ero rẹ lori erongba Tinubu lati du ipo aarẹ han lasiko to n kopa lori eto ori tẹlifisan kan nileesẹ Arise TV lọjọru. Lero ti asaaju ẹgbẹ PDP naa, ara gbogbo awọn eeyan to n sugba Tinubu lati di aarẹ lọdun 2023 ni ara wọn ko ya, wọn si nilo ayẹwo ọpọlọ. Ọmọ igbimọ majẹobajẹ fẹgbẹ oselu PDP naa ni oun yoo kede pe oun kii se ọmọ Naijiria mọ, ti Tinubu ba fi di aarẹ Naijiria lọdun 2023. Bẹẹ ba gbagbe, asaaju ẹgbẹ oselu APC kan, Adeseye Ogunlewe lo ti kọkọ kede pe Tinubu ni oludije to dantọ julọ lati dari Naijiria lọdun 2023. Nigba to n fesi si ọrọ naa siwaju, George ni se ni oun bẹrẹ si ronu nigba ti oun gbọ ọrọ Ogunlewe naa nitori ọkunrin naa ti kọkọ sọrọ saaju lati tabuku Tinubu, to si wa ni akọsilẹ. "Ki lo de tawọn eeyan kii le duro lori ọrọ ti wọn ba sọ gan? Ki lo de ti wọn n jo bi eleegun kiri laarin ọja? Ta ba se agbeyẹwo ọdun mẹjọ ti Tinubu lo bii gomina nipinlẹ Eko, bawo la ti se idajọ rẹ si? Mo setan lati ba Ogunlewe se ariyanjiyan nipa Tinubu nibi kibi, koda, ko baa jẹ ni itẹ oku ni aago mẹta oru, ọrọkọrọ lo n sọ lẹnu. Koda, maa se ohun gbogbo to ba yẹ lati kede pe n ko kii se ọmọ orilẹede yi mọ ti Tinubu ba fi di aarẹ." Bode George, ẹni to ni ọmọ ipinlẹ Eko ni oun, oun si mọ awọn nnkan ti Tinubu se, wa fi ọwọ sọya pe ko yẹ bii aarẹ rara, ti awọn gomina miran to dari ipnilẹ Eko si kaato julọ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58183272 |
5sports
| Barcelona vs PSG: Messi fi àbàrá kékeré gba ńlá lọ́wọ́ Mbappe ni Nou Camp | Igba laa ni, ẹnikan o lo ile aye gbo. Ohun lo difa fun ọdọmọde agbabọọlu PSG, Kylian Mbappe to rọ agbaọjẹ agbabọọlu Barcelona, Lionel Messi loye. Goolu mẹta ọtọtọ ni Mbappe gba sawọn Barcelona nigba ti PSG pokọ iya fun Barcelona nile wọn ni ipele ẹlẹni-mẹrindinlogun idije UEFA Champions League lalẹ ọjọ Iṣẹgun. Ṣe ẹ mọ pe akọda oro ko da bi adagbẹyin. Messi lo kọkọ gba pẹnariti wọle PSG lai mọ pe o kọ lẹta si iya ni. Ṣugbọn goolu mẹrin ni Mbappe ati Moise Kean fi da pada lẹyin ti wọn lu Barca mọlẹ bi aṣọ ofi pẹlu ami ayo mẹrin sí ẹyọkan. Iti ọgẹdẹ ti ko to ohun ti a n yọ ada si ni PSG fi ọrọ Barcelona ṣe ni Nou Camp tori elege ara PSG, Neymar gan an ko lanfaani lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhún lẹyin to ti fi ẹsẹ ṣeṣe tẹlẹ. O ṣeeṣe ki Neymar kopa ninu ipele keji ifẹsẹwọnṣẹ ọhun ti yoo waye logunjo, oṣu kẹta ọdun yìí niluu Paris. | Barcelona vs PSG: Messi fi àbàrá kékeré gba ńlá lọ́wọ́ Mbappe ni Nou Camp Igba laa ni, ẹnikan o lo ile aye gbo. Ohun lo difa fun ọdọmọde agbabọọlu PSG, Kylian Mbappe to rọ agbaọjẹ agbabọọlu Barcelona, Lionel Messi loye. Goolu mẹta ọtọtọ ni Mbappe gba sawọn Barcelona nigba ti PSG pokọ iya fun Barcelona nile wọn ni ipele ẹlẹni-mẹrindinlogun idije UEFA Champions League lalẹ ọjọ Iṣẹgun. Ṣe ẹ mọ pe akọda oro ko da bi adagbẹyin. Messi lo kọkọ gba pẹnariti wọle PSG lai mọ pe o kọ lẹta si iya ni. Ṣugbọn goolu mẹrin ni Mbappe ati Moise Kean fi da pada lẹyin ti wọn lu Barca mọlẹ bi aṣọ ofi pẹlu ami ayo mẹrin sí ẹyọkan. Iti ọgẹdẹ ti ko to ohun ti a n yọ ada si ni PSG fi ọrọ Barcelona ṣe ni Nou Camp tori elege ara PSG, Neymar gan an ko lanfaani lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhún lẹyin to ti fi ẹsẹ ṣeṣe tẹlẹ. O ṣeeṣe ki Neymar kopa ninu ipele keji ifẹsẹwọnṣẹ ọhun ti yoo waye logunjo, oṣu kẹta ọdun yìí niluu Paris. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-56094403 |
3politics
| Ondo Governorship Election: Díẹ ló kú kí wọn yọ Akeredolu ní ip`o Gomin`a, orí ló koyọ | Adajọ mẹrin ninu meje, lo fọwọ sii pe ki gomina Akeredolu wa nipo ti mẹta si sọ wi pe ko lẹtọ lati di ipo naa mu(4-3). Agbẹjọro Agba, Festus Keyamo ti kesi ẹgbẹ oselu APC lati ṣọra lori idibo abẹle to yẹ ko wale ni opin ọṣẹ lati yan awọn adari ẹgbẹ ni wọọdu ati ni ipinlẹ kọọkan. Eyi ko ṣeyin idajọ ileẹjọ to gaju lo lorileẹde Naijiria lori ẹjọ ti oldije lẹgbẹ oṣelu PDP fun ipo gomina nipinlẹ Ondo, Eyitayọ Jegede pe lati sọ wi pe Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ko laṣẹ lati di ipo gomina mu nitori alaga ẹgbẹ fidiẹ, Mala Buni jẹ gomina ipinlẹ Yobe. Keyamo to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ati minisita fun ọrọ igbanisiṣẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ si ẹgbẹ APC, amọ ti awon oniroyin gbe jade ni Gomina Akeredolu ko ba kuna ni ileẹjọ kani Jegede pe ẹjọ mọ Gomina Buni lasiko to lọ si ileẹjọ kotẹmilọrun. ''Kekere bayii loku ki Akeredolu sọ ipo rẹ nu ni idajọ ileẹjọ to gajulọ nitori ko ba ofin mu ki ẹnikẹni ti wọn di ibo yan si ipo lorilẹede Naijiria ṣi ma a ṣe iṣe miran tabi di ipo mu, eleyii ti o mu ki Gomina Buni tapa si ofin pẹlu bo ṣe di ipo gomina ati alaga ẹgbẹ oṣelu APC mu.'' ''Adajọ mẹrin ninu meje, lo fọwọ si pe ki gomina Akeredolu wa nipo ti mẹta si sọ wi pe ko lẹtọ lati di ipo naa mu''. ''Ileẹjọ giga ninu idajọ wọn sọ wi pe o lodi sofin bi Gomina Buni ṣe dari eto idibo si ipo gomina nipinlẹ Ondo, amọ nitori Jegede ko pe e ni ẹjọ ni Akeredolu ṣe bori ni ilẹejọ'' ''O ni ipo Buni tapa si aṣe iwe ofin orilẹede Naijiria, ẹka 183 ti ọdun 1999 pe gomina to wa ni ipo ko gbogbo di ipo alaṣẹ miran mu lorilẹede Naijiria.'' '' Kani Jegede pe ẹjọ mọ Buni ninu ipẹjọ rẹ ni, Eyitayo Jegede ati ẹgbẹ oṣelu PDP iba gba ipo gomina mọ Akeredolu lọwọ nitori aibọwọ fun ofin ti Buni tapa si.'' ''Nitori adajọ mẹrin ninu meje, lo fọwọ si pe ki gomina Akeredolu wa nipo ti mẹta si sọ wi pe ko lẹtọ lati di ipo naa mu nitori Gomina Yobe to di ipo alaga ẹgbẹ oṣelu APC mu.'' Nitori naa, Keyamo kesi ẹgbẹ lati tete pe ipade pajawiri ki ọrọ naa ma bẹyin yọ nitori idibo sipo aaṛ ati idibo gbogboogbo to nbọ ni ọdun 2023. Minisita naa ni ti wọn ko ba ṣọra ṣe ki wọn tete yọ Buni kuro ni ipo naa, awọn ẹgbẹ alatako yoo lo lati fi dabaru eto idibo to n bọ lọdun 2023 ati wi pe Buni ko lẹtọ lati pe ipade gbogboogbo kankan. Keyamo wa rọ ẹgbẹ oṣelu APC lati dawọ idibo abẹlẹ ti wọn fẹ ṣe kaakiri ipinlẹ lati yan awọn adari wọọdu ''congress'' ati awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa ni ipinlẹ duro nitori yoo lẹyin ti wọn ba tẹsiwaju. Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Osu Keje, ọdun 2021 lo yẹ ki idibo lati yan adari wọọdu ati ipinlẹ kaakiri orilẹede Naijiria yẹ ko wayẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC. Amọ, iroyin ni ababọ idajọ ileẹjọ gigajulọ lorilẹede Naijiria ti mu ki awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri Naijiria pe ipada pajawiri lati jiroro boya yoo waye tabi ki wọn sun si iwaju. | Ondo Governorship Election: Díẹ ló kú kí wọn yọ Akeredolu ní ip`o Gomin`a, orí ló koyọ Adajọ mẹrin ninu meje, lo fọwọ sii pe ki gomina Akeredolu wa nipo ti mẹta si sọ wi pe ko lẹtọ lati di ipo naa mu(4-3). Agbẹjọro Agba, Festus Keyamo ti kesi ẹgbẹ oselu APC lati ṣọra lori idibo abẹle to yẹ ko wale ni opin ọṣẹ lati yan awọn adari ẹgbẹ ni wọọdu ati ni ipinlẹ kọọkan. Eyi ko ṣeyin idajọ ileẹjọ to gaju lo lorileẹde Naijiria lori ẹjọ ti oldije lẹgbẹ oṣelu PDP fun ipo gomina nipinlẹ Ondo, Eyitayọ Jegede pe lati sọ wi pe Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ko laṣẹ lati di ipo gomina mu nitori alaga ẹgbẹ fidiẹ, Mala Buni jẹ gomina ipinlẹ Yobe. Keyamo to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ati minisita fun ọrọ igbanisiṣẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ si ẹgbẹ APC, amọ ti awon oniroyin gbe jade ni Gomina Akeredolu ko ba kuna ni ileẹjọ kani Jegede pe ẹjọ mọ Gomina Buni lasiko to lọ si ileẹjọ kotẹmilọrun. ''Kekere bayii loku ki Akeredolu sọ ipo rẹ nu ni idajọ ileẹjọ to gajulọ nitori ko ba ofin mu ki ẹnikẹni ti wọn di ibo yan si ipo lorilẹede Naijiria ṣi ma a ṣe iṣe miran tabi di ipo mu, eleyii ti o mu ki Gomina Buni tapa si ofin pẹlu bo ṣe di ipo gomina ati alaga ẹgbẹ oṣelu APC mu.'' ''Adajọ mẹrin ninu meje, lo fọwọ si pe ki gomina Akeredolu wa nipo ti mẹta si sọ wi pe ko lẹtọ lati di ipo naa mu''. ''Ileẹjọ giga ninu idajọ wọn sọ wi pe o lodi sofin bi Gomina Buni ṣe dari eto idibo si ipo gomina nipinlẹ Ondo, amọ nitori Jegede ko pe e ni ẹjọ ni Akeredolu ṣe bori ni ilẹejọ'' ''O ni ipo Buni tapa si aṣe iwe ofin orilẹede Naijiria, ẹka 183 ti ọdun 1999 pe gomina to wa ni ipo ko gbogbo di ipo alaṣẹ miran mu lorilẹede Naijiria.'' '' Kani Jegede pe ẹjọ mọ Buni ninu ipẹjọ rẹ ni, Eyitayo Jegede ati ẹgbẹ oṣelu PDP iba gba ipo gomina mọ Akeredolu lọwọ nitori aibọwọ fun ofin ti Buni tapa si.'' ''Nitori adajọ mẹrin ninu meje, lo fọwọ si pe ki gomina Akeredolu wa nipo ti mẹta si sọ wi pe ko lẹtọ lati di ipo naa mu nitori Gomina Yobe to di ipo alaga ẹgbẹ oṣelu APC mu.'' Nitori naa, Keyamo kesi ẹgbẹ lati tete pe ipade pajawiri ki ọrọ naa ma bẹyin yọ nitori idibo sipo aaṛ ati idibo gbogboogbo to nbọ ni ọdun 2023. Minisita naa ni ti wọn ko ba ṣọra ṣe ki wọn tete yọ Buni kuro ni ipo naa, awọn ẹgbẹ alatako yoo lo lati fi dabaru eto idibo to n bọ lọdun 2023 ati wi pe Buni ko lẹtọ lati pe ipade gbogboogbo kankan. Keyamo wa rọ ẹgbẹ oṣelu APC lati dawọ idibo abẹlẹ ti wọn fẹ ṣe kaakiri ipinlẹ lati yan awọn adari wọọdu ''congress'' ati awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa ni ipinlẹ duro nitori yoo lẹyin ti wọn ba tẹsiwaju. Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Osu Keje, ọdun 2021 lo yẹ ki idibo lati yan adari wọọdu ati ipinlẹ kaakiri orilẹede Naijiria yẹ ko wayẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC. Amọ, iroyin ni ababọ idajọ ileẹjọ gigajulọ lorilẹede Naijiria ti mu ki awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri Naijiria pe ipada pajawiri lati jiroro boya yoo waye tabi ki wọn sun si iwaju. | https://www.bbc.com/yoruba/media-58024327 |
3politics
| PDP Crises: Secondus, Wike, BoT: A kò gbọdọ̀ tún ṣe àṣìṣe tí a fi kùnà ní 2015- PDP | Lẹyin ipade wakati mẹrin ti wọn ṣe nilu Abuja, igbimọ majeobajẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party PDP ko ribi yanju aawọ to jẹ bi ipenija fun ẹgbẹ naa. Ẹnu igbimọ yi ko ko lori boya ki alaga ẹgbẹ naa Uche Secondus ṣi wa lori oye tabi ko fi ipo silẹ gẹgẹ bi awọn ọmọ ẹgbẹ kọọkan ti ṣe n beere. Ohun ti igbimọ naa sọ ni pe awọn yoo ṣe agbekalẹ igbimọ tuntun eleyi ti yoo joko lori ọna ati yanju gbogbo ọrọ to n fa gbọnmi si omi o to. Wàhálà àti ìkùnsínú láàrin ọmọ ẹgbẹ́ PDP, kí ni ọ̀nà àbáyọ? Ṣẹnẹtọ Walid Jibrin lo dari ipade naa eyi ti ko fẹnu ko boya ki wọn daba ijiya fawọn ọmọ ẹgbẹ to lọwọ ninu rukerudo to n damu ẹgbẹ ọhun. Bi nkan ti ṣe ri bayi, ojutu ọrọ ko le ni iyanju ayafi ti ipade yi ba joko jiroro tan. Sẹnẹtọ Bukola Saraki ati Sẹnẹtọ David Mark to ba awọn akọroyin sọrọ kọ lati sọ oju abẹ niko ṣugbọn wọn ni ipade tawọn ṣe so eso rere. Nigba tawọn akọroyin beere lọwọ Bukola Saraki boya wọn yoo jẹ ki igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ naa pari saa wọn, o ni awọn yoo ṣe ipade laarin ọjọ meji si mẹta la ti le mọ ibi ti ọrọ n lọ. Fakinfa laarin alaga ẹgbẹ PDP Uche Secondus ati Gomina Nyesom Wike wa lara nkan tawọn eeyan kan tọka si pe o n da wahala silẹ ninu ẹgbẹ. Kí ni ọ̀nà àbáyọ sí aáwọ̀ tó fẹ́ dojú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP bolẹ̀? Bo tilẹ jẹ wi pe awọn mejeeji ko jade lati sọ pe ede aiyede wa, pupọ lo gbagbọ pe Gomina Wike ko dunnu si iṣakoso Secondus to si n pete pero lati yọ kuro lori oye. Oṣu mẹta si mẹrin lo ku ti saa Secondus yoo fi pari ki awọn ọmọ ẹgbẹ to yan alaga mi. Iṣẹlẹ ikọwefiposilẹ awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya meje ninu ẹgbẹ naa tubọ mu ki awọn eeyan sọ pe o ṣeese ki wọn yẹ aga nidi Secondus nibi ipade awọn majeobajẹ ẹgbẹ. Amọ bi nkan ti ṣe ri yi, o ṣeeṣe ki wọn ri ọna naa yanju ti igbimọ majeobaje ba tun ṣe ipade lori ọrọ itẹsiwaju ẹgbẹ Ki ṣe akọkọ ree ti wahala yoo de ba ẹgbẹ oṣelu PDP. Lọpọ igba ti ọdun idibo ba ti n sunmọ, orisirisi wahala lo maa n bẹ silẹ eyi to maa n ṣokunfa ki wọn yọ alaga ẹgbẹ naa. Ninu ọrọ rẹ sawọn ọmọ ẹgbẹ,alaga igbimọ majeobajẹ ẹgbẹ Senatọ Walid Jibrin kesi awọn agbaagba ẹgbẹ lati woye nipa wahala to yọ awọn alaga ẹgbẹ to ṣaaju. O ni bayi tawọn ọmọ Naijiria n foju wo PDP gẹgẹ bi ẹgbẹ ti yoo gba awọn ọmọ Naijiria silẹ, ko tọ ki wọn tun wa sa ara wọn sinu wahala ija ti ko nidi. ''Ki a baa le ṣe ẹkunrẹrẹ aseyọri a ni lati jawọ nibi gbogbo ija ti ko nidi laarin ara wa ki a ba ma ṣe ṣakoba fun adisọkan ẹgbẹ wa'' Ninu awọn alaga ẹgbẹ ana ti ko pari saa wọn labẹ ẹgbẹ PDP ni a ti ri -Chief Audu Ogbeh -Okwesilieze Nwodo -Bamanga Tukur -Ahmed Muazu ati -Ali Modu Sheriff Wo àwòrán ìgbéyàwó ọkùnrin tó gbé obìnrin mẹ́rin níyàwó lọ́jọ́ kan ṣoṣo A ti mú afurasí darandaran méjì tó ń da màálù tó kan ọmọ oṣù mẹ́ta pa- Ọlọ́pàá Òjò àrọ̀rọ̀dá gbẹ̀mí èèyàn mẹ́ta ní Oshogbo,ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò Níbo ló kù tí Messi yóò lọ báyìí? Kò sí olóṣèlú kankan tó ń pàṣẹ fún wa pé kí á máa ti aráálú mọ́lé- DSS Àwọn ìlúmọ̀ọ́ká Mẹ́wàá to kú nínú oṣù keje odun 2021 Ẹran Akíka(Pangolin) àti ìwo Erin d'ẹ́rù b'olẹ̀, ìjọba f'òfin gba bílíọ́nù 22 ẹran ara wọn | PDP Crises: Secondus, Wike, BoT: A kò gbọdọ̀ tún ṣe àṣìṣe tí a fi kùnà ní 2015- PDP Lẹyin ipade wakati mẹrin ti wọn ṣe nilu Abuja, igbimọ majeobajẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party PDP ko ribi yanju aawọ to jẹ bi ipenija fun ẹgbẹ naa. Ẹnu igbimọ yi ko ko lori boya ki alaga ẹgbẹ naa Uche Secondus ṣi wa lori oye tabi ko fi ipo silẹ gẹgẹ bi awọn ọmọ ẹgbẹ kọọkan ti ṣe n beere. Ohun ti igbimọ naa sọ ni pe awọn yoo ṣe agbekalẹ igbimọ tuntun eleyi ti yoo joko lori ọna ati yanju gbogbo ọrọ to n fa gbọnmi si omi o to. Wàhálà àti ìkùnsínú láàrin ọmọ ẹgbẹ́ PDP, kí ni ọ̀nà àbáyọ? Ṣẹnẹtọ Walid Jibrin lo dari ipade naa eyi ti ko fẹnu ko boya ki wọn daba ijiya fawọn ọmọ ẹgbẹ to lọwọ ninu rukerudo to n damu ẹgbẹ ọhun. Bi nkan ti ṣe ri bayi, ojutu ọrọ ko le ni iyanju ayafi ti ipade yi ba joko jiroro tan. Sẹnẹtọ Bukola Saraki ati Sẹnẹtọ David Mark to ba awọn akọroyin sọrọ kọ lati sọ oju abẹ niko ṣugbọn wọn ni ipade tawọn ṣe so eso rere. Nigba tawọn akọroyin beere lọwọ Bukola Saraki boya wọn yoo jẹ ki igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ naa pari saa wọn, o ni awọn yoo ṣe ipade laarin ọjọ meji si mẹta la ti le mọ ibi ti ọrọ n lọ. Fakinfa laarin alaga ẹgbẹ PDP Uche Secondus ati Gomina Nyesom Wike wa lara nkan tawọn eeyan kan tọka si pe o n da wahala silẹ ninu ẹgbẹ. Kí ni ọ̀nà àbáyọ sí aáwọ̀ tó fẹ́ dojú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP bolẹ̀? Bo tilẹ jẹ wi pe awọn mejeeji ko jade lati sọ pe ede aiyede wa, pupọ lo gbagbọ pe Gomina Wike ko dunnu si iṣakoso Secondus to si n pete pero lati yọ kuro lori oye. Oṣu mẹta si mẹrin lo ku ti saa Secondus yoo fi pari ki awọn ọmọ ẹgbẹ to yan alaga mi. Iṣẹlẹ ikọwefiposilẹ awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya meje ninu ẹgbẹ naa tubọ mu ki awọn eeyan sọ pe o ṣeese ki wọn yẹ aga nidi Secondus nibi ipade awọn majeobajẹ ẹgbẹ. Amọ bi nkan ti ṣe ri yi, o ṣeeṣe ki wọn ri ọna naa yanju ti igbimọ majeobaje ba tun ṣe ipade lori ọrọ itẹsiwaju ẹgbẹ Ki ṣe akọkọ ree ti wahala yoo de ba ẹgbẹ oṣelu PDP. Lọpọ igba ti ọdun idibo ba ti n sunmọ, orisirisi wahala lo maa n bẹ silẹ eyi to maa n ṣokunfa ki wọn yọ alaga ẹgbẹ naa. Ninu ọrọ rẹ sawọn ọmọ ẹgbẹ,alaga igbimọ majeobajẹ ẹgbẹ Senatọ Walid Jibrin kesi awọn agbaagba ẹgbẹ lati woye nipa wahala to yọ awọn alaga ẹgbẹ to ṣaaju. O ni bayi tawọn ọmọ Naijiria n foju wo PDP gẹgẹ bi ẹgbẹ ti yoo gba awọn ọmọ Naijiria silẹ, ko tọ ki wọn tun wa sa ara wọn sinu wahala ija ti ko nidi. ''Ki a baa le ṣe ẹkunrẹrẹ aseyọri a ni lati jawọ nibi gbogbo ija ti ko nidi laarin ara wa ki a ba ma ṣe ṣakoba fun adisọkan ẹgbẹ wa'' Ninu awọn alaga ẹgbẹ ana ti ko pari saa wọn labẹ ẹgbẹ PDP ni a ti ri -Chief Audu Ogbeh -Okwesilieze Nwodo -Bamanga Tukur -Ahmed Muazu ati -Ali Modu Sheriff Wo àwòrán ìgbéyàwó ọkùnrin tó gbé obìnrin mẹ́rin níyàwó lọ́jọ́ kan ṣoṣo A ti mú afurasí darandaran méjì tó ń da màálù tó kan ọmọ oṣù mẹ́ta pa- Ọlọ́pàá Òjò àrọ̀rọ̀dá gbẹ̀mí èèyàn mẹ́ta ní Oshogbo,ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò Níbo ló kù tí Messi yóò lọ báyìí? Kò sí olóṣèlú kankan tó ń pàṣẹ fún wa pé kí á máa ti aráálú mọ́lé- DSS Àwọn ìlúmọ̀ọ́ká Mẹ́wàá to kú nínú oṣù keje odun 2021 Ẹran Akíka(Pangolin) àti ìwo Erin d'ẹ́rù b'olẹ̀, ìjọba f'òfin gba bílíọ́nù 22 ẹran ara wọn | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58111037 |
5sports
| Ìdí rèé tí Man U ṣe já Odion Ighalo sílẹ̀ nínú ìgbáradì rẹ̀ tí yóò wáyé ni Spain | Odion Ighalo ko ni ba awọn akẹgbẹ ni Manchester United kopa ninu igabradi wọn ti yoo waye lorilẹ-ede Spain nitori ibẹru aisan Coronavirus. Ẹlẹsẹ ayo ọhun darapọ Manchester United lati ẹgbẹ agbabọọlu Shanghai Shenhua lorilẹ-ede China, nibi ti aisan naa ti kọkọ bẹrẹ. Wọn ni ti Ighalo ba tẹlẹ awọn akẹgbẹ rẹ lo si Spain, o ṣeṣe ki ileeṣẹ aṣọbode ilẹ Gẹẹsi ma gba a laaye lati pada si orilẹ-ede naa nitori ibẹru aisan ọhun. Akọnimọgba Manchester United, Ole Gunnar Solskjaer sọ fun awọn oniroyin pe yoo jẹ didun inu Ighalo lati darapọ mọ awọn akẹgbẹ rẹ. O ni "Nitori bi ọrọ ṣe ri lọwọ yii ni China, ko da wa loju pe wọn yoo gba Igahlo laye lati pada wọ ilẹ Gẹẹsi to ba lee jade." Solskjaer tẹsiwaju pe, nitori naa, Ighalo yoo ṣi wa ni ilẹ Gẹẹsi fun akoko yii. Akọnimọgba naa ni igbesẹ ọhun jẹ fun igba diẹ lati le mọ ibi ti ọrọ aisan Coronavirus naa yoo yọri si. Aisan coronavirus ọhun to bẹrẹ lorilẹ-ede China ti mu ọpọlọpọ ẹmi lọ, ti awọn onimọ ijinlẹ si ti n wa ojutu sii. | Ìdí rèé tí Man U ṣe já Odion Ighalo sílẹ̀ nínú ìgbáradì rẹ̀ tí yóò wáyé ni Spain Odion Ighalo ko ni ba awọn akẹgbẹ ni Manchester United kopa ninu igabradi wọn ti yoo waye lorilẹ-ede Spain nitori ibẹru aisan Coronavirus. Ẹlẹsẹ ayo ọhun darapọ Manchester United lati ẹgbẹ agbabọọlu Shanghai Shenhua lorilẹ-ede China, nibi ti aisan naa ti kọkọ bẹrẹ. Wọn ni ti Ighalo ba tẹlẹ awọn akẹgbẹ rẹ lo si Spain, o ṣeṣe ki ileeṣẹ aṣọbode ilẹ Gẹẹsi ma gba a laaye lati pada si orilẹ-ede naa nitori ibẹru aisan ọhun. Akọnimọgba Manchester United, Ole Gunnar Solskjaer sọ fun awọn oniroyin pe yoo jẹ didun inu Ighalo lati darapọ mọ awọn akẹgbẹ rẹ. O ni "Nitori bi ọrọ ṣe ri lọwọ yii ni China, ko da wa loju pe wọn yoo gba Igahlo laye lati pada wọ ilẹ Gẹẹsi to ba lee jade." Solskjaer tẹsiwaju pe, nitori naa, Ighalo yoo ṣi wa ni ilẹ Gẹẹsi fun akoko yii. Akọnimọgba naa ni igbesẹ ọhun jẹ fun igba diẹ lati le mọ ibi ti ọrọ aisan Coronavirus naa yoo yọri si. Aisan coronavirus ọhun to bẹrẹ lorilẹ-ede China ti mu ọpọlọpọ ẹmi lọ, ti awọn onimọ ijinlẹ si ti n wa ojutu sii. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51429558 |
5sports
| Omijé gbojú Anthony Joshua lẹ́yìn tó lulẹ̀ níwájú Oleksandr Usyk lẹ́ẹ̀kejì | Niṣe lomije n bọ loju gbajumọ akanṣẹgbayi ọmọ orilẹede England, Anthony Joshua lẹyin to padanu ifẹsẹwọnsẹ ẹṣẹ kikan laarin oun ati Oleksandr Usyk lọjọ Satide mọ Ọjọ Aiku. Bo tilẹ jẹ pe onka awọn alamojuto ifẹsẹwọnsẹ ẹṣẹ kikan naa lo fun Usyk ni bẹliti igbanu ẹyẹ olubori nilu Jeddah lorilẹede Saudi Arabia, Joshua ṣalaye nigba ti wọn bii lere ọrọ pe, “inu n bimi gidi gan an ni, o dun mi de isalẹ ọkan mi” Lẹyin to sọ eyi tan, Joshua fọwọ boju rẹ o si mi kanlẹ. O ni awọn, “ipenija kan ti mo n koju n ni ipa lara mi ṣugbọn n ko ni jẹ ki ijakulẹ ija naa gbe mi ṣubu bi o tilẹ jẹ pe yoo nira diẹ” Joshua ti gba ami ẹyẹ goolu ẹṣẹ kikan ni idije Olympics lọdun 2012 nilu London. Lẹyin eyi lo bori awọn ija nejilelogun to kọkọ ja gẹgẹ bi akanṣẹjẹun. Anthony Joshua ti padanu mẹta ninu awọn ija marun to ja gbẹyin bayii, igba keji si niyi ni tẹlentẹle ti yoo lulẹ niwaju Usyk ọmọ orilẹede Ukraine. Kamaru Usman pẹlu lilẹ ni idije ijakadi igbalode UFC 278. Kamaru Usman padanu idije ijakadi igbalode UFC 278 ni ipele Welterweight to wa. | Omijé gbojú Anthony Joshua lẹ́yìn tó lulẹ̀ níwájú Oleksandr Usyk lẹ́ẹ̀kejì Niṣe lomije n bọ loju gbajumọ akanṣẹgbayi ọmọ orilẹede England, Anthony Joshua lẹyin to padanu ifẹsẹwọnsẹ ẹṣẹ kikan laarin oun ati Oleksandr Usyk lọjọ Satide mọ Ọjọ Aiku. Bo tilẹ jẹ pe onka awọn alamojuto ifẹsẹwọnsẹ ẹṣẹ kikan naa lo fun Usyk ni bẹliti igbanu ẹyẹ olubori nilu Jeddah lorilẹede Saudi Arabia, Joshua ṣalaye nigba ti wọn bii lere ọrọ pe, “inu n bimi gidi gan an ni, o dun mi de isalẹ ọkan mi” Lẹyin to sọ eyi tan, Joshua fọwọ boju rẹ o si mi kanlẹ. O ni awọn, “ipenija kan ti mo n koju n ni ipa lara mi ṣugbọn n ko ni jẹ ki ijakulẹ ija naa gbe mi ṣubu bi o tilẹ jẹ pe yoo nira diẹ” Joshua ti gba ami ẹyẹ goolu ẹṣẹ kikan ni idije Olympics lọdun 2012 nilu London. Lẹyin eyi lo bori awọn ija nejilelogun to kọkọ ja gẹgẹ bi akanṣẹjẹun. Anthony Joshua ti padanu mẹta ninu awọn ija marun to ja gbẹyin bayii, igba keji si niyi ni tẹlentẹle ti yoo lulẹ niwaju Usyk ọmọ orilẹede Ukraine. Kamaru Usman pẹlu lilẹ ni idije ijakadi igbalode UFC 278. Kamaru Usman padanu idije ijakadi igbalode UFC 278 ni ipele Welterweight to wa. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cl57qqnyj99o |
3politics
| Atiku: Igun olùjẹ́jọ́ gan kò fèsì sí àṣìṣe ìṣirò tí ẹlẹ́rìí kan mẹ́nubà pé INEC ṣe | Ẹgbẹ oselu PDP ati oludije rẹ fun ipo aarẹ to kọja, Atiku Abubakar ti kasẹ atotonu wọn nilẹ niwaju igbimọ to n gbọ ẹjọ ẹhonu to suyọ lẹyin ibo naa. Nigba ti wọn n kalẹ alaye ẹhonu wọn ọhun nilẹ, wọn fẹsun kan pe wọn ja awọn lole ni nidi akojọpọ esi ibo aarẹ eyi to mu ki wọn fidi rẹmi ninu abajade esi ibo ọhun. Ninu alaye wọn, eyi ti asaaju ikọ agbẹjọro to n soju igun mejeeji, agba amofin Livy Uzoukwu gbe siwaju igbimọ olugbẹjọ naa, o ni asise waye nidi isiro awọn esi ibo aarẹ ni ipinlẹ mọkanla. Gẹgẹ bi igun olupẹjọ naa ti wi, awọn ipinlẹ mọkanla ọhun ti asise isiro esi ibo ti waye ni ipinlẹ Bauchi, Borno, Gombe, Jigawa, Kaduna, Kano, Katsina, Kebbi, Niger, Yobe ati Zamfara. PDP ati Atiku ni, to ba jẹ pe wọn ka awọn esi ibo naa bo se yẹ ni, awọn ko ba fi ibo to to 222,332 na aarẹ Muhammadu Buhari, tii se alatako latinu ẹgbẹ oselu APC, ti wọn kede pe o jawe olubori. Ikọ olujẹjọ ni bi akojọpọ esi ibo aarẹ naa ba lọ bo se yẹ ko lọ, apapọ esi ibo to yẹ ki ẹgbẹ oselu PDP ati oludije rẹ fun ibo aarẹ gba ni 9,426,082, eyi ti wọn lo tayọ apapọ ibo Buhari ati APC tii se 9, 203,750. Wọn wa kadi ọrọ wọn nilẹ pe lasiko ti igun olujẹjọ gan n kadi ọrọ rẹ nilẹ, ko tako ẹri ti ọkan lara awọn ẹlẹri ti wọn ko wa siwaju igbimọ naa, tii se akọsẹmọsẹ olusiro gbe kalẹ, eyi to n tọkasi pe asise wa ninu esi ibo ti ajọ INEC kede. | Atiku: Igun olùjẹ́jọ́ gan kò fèsì sí àṣìṣe ìṣirò tí ẹlẹ́rìí kan mẹ́nubà pé INEC ṣe Ẹgbẹ oselu PDP ati oludije rẹ fun ipo aarẹ to kọja, Atiku Abubakar ti kasẹ atotonu wọn nilẹ niwaju igbimọ to n gbọ ẹjọ ẹhonu to suyọ lẹyin ibo naa. Nigba ti wọn n kalẹ alaye ẹhonu wọn ọhun nilẹ, wọn fẹsun kan pe wọn ja awọn lole ni nidi akojọpọ esi ibo aarẹ eyi to mu ki wọn fidi rẹmi ninu abajade esi ibo ọhun. Ninu alaye wọn, eyi ti asaaju ikọ agbẹjọro to n soju igun mejeeji, agba amofin Livy Uzoukwu gbe siwaju igbimọ olugbẹjọ naa, o ni asise waye nidi isiro awọn esi ibo aarẹ ni ipinlẹ mọkanla. Gẹgẹ bi igun olupẹjọ naa ti wi, awọn ipinlẹ mọkanla ọhun ti asise isiro esi ibo ti waye ni ipinlẹ Bauchi, Borno, Gombe, Jigawa, Kaduna, Kano, Katsina, Kebbi, Niger, Yobe ati Zamfara. PDP ati Atiku ni, to ba jẹ pe wọn ka awọn esi ibo naa bo se yẹ ni, awọn ko ba fi ibo to to 222,332 na aarẹ Muhammadu Buhari, tii se alatako latinu ẹgbẹ oselu APC, ti wọn kede pe o jawe olubori. Ikọ olujẹjọ ni bi akojọpọ esi ibo aarẹ naa ba lọ bo se yẹ ko lọ, apapọ esi ibo to yẹ ki ẹgbẹ oselu PDP ati oludije rẹ fun ibo aarẹ gba ni 9,426,082, eyi ti wọn lo tayọ apapọ ibo Buhari ati APC tii se 9, 203,750. Wọn wa kadi ọrọ wọn nilẹ pe lasiko ti igun olujẹjọ gan n kadi ọrọ rẹ nilẹ, ko tako ẹri ti ọkan lara awọn ẹlẹri ti wọn ko wa siwaju igbimọ naa, tii se akọsẹmọsẹ olusiro gbe kalẹ, eyi to n tọkasi pe asise wa ninu esi ibo ti ajọ INEC kede. | https://www.bbc.com/yoruba/49367094 |
5sports
| Manchester United vs Leicester: Leicester City ṣẹ́ṣó ìyà fún Man United, Man City gba ife ẹ̀yẹ Premier League ti sáà yìí | Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ti gba ife ẹyẹ Premier League fun saa bọọlu yii. Man City gba ife naa lẹyin ti Leicestrer City lu Man U mọle pẹlu ami ayo meji sẹyọkan lọjọ Iṣẹgun. Ami ayo mẹwaa ni Man City fi n ṣiwaju United ninu eyi ti wọn si ni ifẹsẹwọnsẹ mẹta pere to ku ti wọn yoo gba ti saa yii yoo fi pari. Igba kẹta ti Man City yoo gba ife ẹyẹ Premier League ree laarin ọdun mẹrin ti Pep Guardiola ti di akọnimọọgba wọn. | Manchester United vs Leicester: Leicester City ṣẹ́ṣó ìyà fún Man United, Man City gba ife ẹ̀yẹ Premier League ti sáà yìí Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ti gba ife ẹyẹ Premier League fun saa bọọlu yii. Man City gba ife naa lẹyin ti Leicestrer City lu Man U mọle pẹlu ami ayo meji sẹyọkan lọjọ Iṣẹgun. Ami ayo mẹwaa ni Man City fi n ṣiwaju United ninu eyi ti wọn si ni ifẹsẹwọnsẹ mẹta pere to ku ti wọn yoo gba ti saa yii yoo fi pari. Igba kẹta ti Man City yoo gba ife ẹyẹ Premier League ree laarin ọdun mẹrin ti Pep Guardiola ti di akọnimọọgba wọn. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57075232 |
3politics
| PDP Presidential primaries: Atiku Abubakar, Peter Obi, Nyesom Wike àti àwọn míì tó n wà tíkẹ́ẹ̀tì láti dù ipò ààrẹ lábẹ́ àsìá PDP | Aaya ti bẹ silẹ bayii tawọn to ndu tikẹẹti lati dije ipo aarẹ lọdun 2023 ni Naijiria ti bẹ si aare. Pupọ ti n ferongba han lati dije ipo to gajulọ ni Naijiria. Amọ ninu ẹgbẹ oṣelu alatako PDP ni Naijiria, awọn to ti ferongba silẹ fun tikẹẹti oludije ipo aarẹ ti le ni mẹwaa Mẹrin ninu wọn jẹ gomina to wa lori oye ninu mọkandinlogun ti ẹgbẹ naa ni ni Naijiria. Yatọ si akẹgbẹ wọn APC to ti lawọn yoo tẹle ilana ''zoning'' lori ipo oludije aarẹ, PDP ko ti sọ iha Naijiria ti oludije ti gbọdọ wa Eleyi lo jẹ ki awọn oludije jakejado Naijiria maa fẹrongba han. Ninu awọn oludije yi la ti ri Atiku Abubakar,Bukola Saraki, Ayo Fayose, Peter Obi Mohammed Hayatu-Deen, Sam Ohabunwa ati Pius Ayim. Awọn miran ni Nyesom Wike, Aminu Tambuwal, Bala Mohammed, Nwachukwu Anakwenze Emmanuel Udom ati Dele Momodu. Gbogbo awọn taa ka silẹ yii lo ti gba fọọmu lati kopa ninu idibo abẹnu ti yoo waye loṣu to n bọ. Igba ẹlẹẹkẹfa ree ti igbakeji aarẹ tẹlẹ yii yoo du ipo Aarẹ. Ipinlẹ Adamawa lo ti wa ni ila oorun Ariwa Naijiria. Oloṣelu ati oniṣowo ni Atiku. O ṣaaju dije dupo gomina Adamawa lẹẹmeji, 1990 ati ni 1998 ko to pada di igbakeji aarẹ ni 1999. Ni 1993 o du ipo aarẹ labẹ asia Social Democratic party nibi to ti fidirẹmi lọwọ Moshood Abiola ati Baba Gana Kingibe. Ni bayi to pe ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin, Atiku ṣi loun ni igbagbọ pe o yẹ ki wọn fun oun laaye lati dari Naijiria. Lasiko to n kede erongba rẹ lati du ipo Aarẹ, Atiku sọ pe koko marun un loun yoo gbajumọ, aabo, ọrọ aje, ẹkọ, isọkan Naijiria ati gbigbe agbara fawọn ipinlẹ. Idile oloṣelu ni Bukola Saraki ti wa. O fi igba kan jẹ Gomina ni ipinlẹ Kwara to si ṣe saa meji ni ijọba laarin 2003-2011. Lẹyin igba naa o di aarẹ ile aṣofin agba Naijiria ldun 2015. Inu ẹgbẹ PDP lo ti kọkọ bẹrẹ irinajo rẹ ko to pada si APC ko tun to pada si PDP ṣaaju idibo 2019. Saa kan lo lo lori ipo aarẹ ile aṣofin agba ko to fidi rẹmi ninu idibo to waye lẹyin. Ẹni ọdun mọkandinlọgọta ni Saraki ṣe to si jẹ onimọ nipa ilera ko to di oloṣelu. Sam Ohabunwa ni oludije ti ọjọ ori rẹ dagba julọ ṣikeji ninu awọn to n wa tikẹẹti PDP. Ipinlẹ Abia lo ti wa ni ilẹ Igbo Naijiria. O jẹ akọṣẹmọṣ apoogun to si tun jẹ oloṣelu. Saaju asiko yi o ti jẹ alaga igbimọ to n risi ọrọ aje Naijiria oun si ni alaga akọkọ fawọn ẹgbẹ awọn to peelo nkan ni Naijiria. Ohabunwa sọ pe oun ni iriri toun fi le sọ Naijiria di orileede ti yoo maa da pese ohun elo gbogbo to ba nilo. O ni Naijiria ti yapa bayi ati pe oun fẹ mu isọkan pada wa ki nkan si burẹkẹ fawọn eeyan orileede Naijiria. Tambuwal ti ṣe Gomina lẹẹmeeji ni ipinlẹ Sokoto. Ṣaaju lo jẹ ipo olori ile aṣojuṣofin Naijiria laarin ọdun 2011-2015. O gbero lati jẹ Aarẹ Naijiria lọdun 2019 ṣugbọn o kuna. Ninu awọn alatilẹyin rẹ nigba naa ni ọrẹ rẹ Gomina Nyesom Wike ipinlẹ Rivers. Amọ bayi ẹni ọdun mẹrindinlọgọta yi n wa tikẹẹti ipo aarẹ PDP pẹlu ọrẹ rẹ Wike. O ni erongba oun ni lati wa ojutu si gbogbo ipenija to n koju Naijiria, Gomina lọwọlọwọ ni Nyesom Wike j ni ipinlẹ Rivers. Agbẹjọro ni Wike to si di alaga ijọba ibilẹ Obio-Akpor lọdun 1999. Lọdun 2007 o riṣẹ gẹgẹ bi olori oṣiṣẹ ile ijọba fun Gomina Rotimi Amaechi Nigba ti yoo fi di 2011, Aarẹ tẹlẹ Goodluck Jonathan yan sipo Minisita feto ẹkọ. Lọdun 2015 lo di Gomina Rivers to si n ṣe saa keji rẹ lọwọ bayii. O ni ijọba oun gẹgẹ bi aarẹ yoo wa ojutu si gbogbo ipenija didari Naijiria toun yoo si sọ eto ọrọ aje ji pada. Gomina lọwọ bayi ni ipinlẹ Bauchi ni Bala Mohammede jẹ. Ṣaaju o ti jẹ Sẹnẹtọ laarin ọdun 2007-2010. Ni 2010 o di Minisita fun olu ilu Naijiria, FCT ti eleyi si tan irawọ rẹ soke gẹgẹ bi oloṣelu. Lọdun 2019 o jawe olubori ninu idibo to si wọle sipo Gomina Bauchi Ẹni ọdun mẹtalelọgọta yii sọ pe oun nigba pe oun le mu iyipada ba Naijiria Oloṣelu ati oniṣowo ni Peter Obi jẹ. O fi igba kan jẹ Gomina ni ipinlẹ Anambra to si lo saa meji laarin 2008-2018 Obi jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Grand Alliance (Apga) ki o to darapọ mọ PDP ni 2017. O tun jẹ eeyan kan to nimọ nipa eto ọrọ aje. Lọdun 2019 o jade gẹgẹ bi igbakeji Atiku Abubakar fun ipo aarẹ. Amọ lọdun 2022 o ni oun gaan loun f du ipo aarẹ. Ipese iṣẹ, mimu agbega ba eto ọrọ aje Naijiria ati eto ẹkọ ni afojusun Peter Obi to ba jẹ aarẹ Naijiria. Oṣokomọlẹ Gomina nigba kan ri ni Ayodele Fayose jẹ. O ṣe Gomina ni saa meji. Igba akọkọ ni laarin ọdun 2003 si 2006. O fipo silẹ ko to tun pada wa di Gomina ni igba ẹlẹẹkeji iyẹn laarin ọdun 2014-2018. Ẹni ọdun mejilelọgọta ni Fayose n ṣe. O ni oun ni iriri lati le mu iyipada ba Naijiria. Laarin ọjọ Kẹrin oṣu Kẹrin si ọjọ Kẹta oṣu Kẹfa lawọn ẹgbẹ oṣelu ni lati ṣeto idibo abẹnu kiwọn si yanju aawọ kankan to ba tẹyin rẹ wa. Eyi lọrọ to wa ninu ilana idibo ti ajọ eleto idibo INEC gbe jade. Wọn le lo ilana taarara, ẹlẹburu tabi ki wọn fẹnu ko lati yan oludije to ba wu wọn. Amọ ṣa INEC ni gbogbo awọn aṣoju ẹgbẹ lo gbọdọ buwọlu ki wọn sikopa ninu eto afẹnukoyan aṣoju yi taa mọ si "consensus." Gbogbo awọn aṣoju yi yoo si peju lati ipinlẹ mẹrindinlogoji si ibudo ti wọn ba yan lati ṣe ipade apero gbogboogbo ẹgbẹ wọn. A o maa fi orukọ awọn oludije mii sọwọ lori apilkọ yi bi wọn ba ti ṣe n yọju.Ẹ maa ba wa fkan ba eto naa bọ. | PDP Presidential primaries: Atiku Abubakar, Peter Obi, Nyesom Wike àti àwọn míì tó n wà tíkẹ́ẹ̀tì láti dù ipò ààrẹ lábẹ́ àsìá PDP Aaya ti bẹ silẹ bayii tawọn to ndu tikẹẹti lati dije ipo aarẹ lọdun 2023 ni Naijiria ti bẹ si aare. Pupọ ti n ferongba han lati dije ipo to gajulọ ni Naijiria. Amọ ninu ẹgbẹ oṣelu alatako PDP ni Naijiria, awọn to ti ferongba silẹ fun tikẹẹti oludije ipo aarẹ ti le ni mẹwaa Mẹrin ninu wọn jẹ gomina to wa lori oye ninu mọkandinlogun ti ẹgbẹ naa ni ni Naijiria. Yatọ si akẹgbẹ wọn APC to ti lawọn yoo tẹle ilana ''zoning'' lori ipo oludije aarẹ, PDP ko ti sọ iha Naijiria ti oludije ti gbọdọ wa Eleyi lo jẹ ki awọn oludije jakejado Naijiria maa fẹrongba han. Ninu awọn oludije yi la ti ri Atiku Abubakar,Bukola Saraki, Ayo Fayose, Peter Obi Mohammed Hayatu-Deen, Sam Ohabunwa ati Pius Ayim. Awọn miran ni Nyesom Wike, Aminu Tambuwal, Bala Mohammed, Nwachukwu Anakwenze Emmanuel Udom ati Dele Momodu. Gbogbo awọn taa ka silẹ yii lo ti gba fọọmu lati kopa ninu idibo abẹnu ti yoo waye loṣu to n bọ. Igba ẹlẹẹkẹfa ree ti igbakeji aarẹ tẹlẹ yii yoo du ipo Aarẹ. Ipinlẹ Adamawa lo ti wa ni ila oorun Ariwa Naijiria. Oloṣelu ati oniṣowo ni Atiku. O ṣaaju dije dupo gomina Adamawa lẹẹmeji, 1990 ati ni 1998 ko to pada di igbakeji aarẹ ni 1999. Ni 1993 o du ipo aarẹ labẹ asia Social Democratic party nibi to ti fidirẹmi lọwọ Moshood Abiola ati Baba Gana Kingibe. Ni bayi to pe ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin, Atiku ṣi loun ni igbagbọ pe o yẹ ki wọn fun oun laaye lati dari Naijiria. Lasiko to n kede erongba rẹ lati du ipo Aarẹ, Atiku sọ pe koko marun un loun yoo gbajumọ, aabo, ọrọ aje, ẹkọ, isọkan Naijiria ati gbigbe agbara fawọn ipinlẹ. Idile oloṣelu ni Bukola Saraki ti wa. O fi igba kan jẹ Gomina ni ipinlẹ Kwara to si ṣe saa meji ni ijọba laarin 2003-2011. Lẹyin igba naa o di aarẹ ile aṣofin agba Naijiria ldun 2015. Inu ẹgbẹ PDP lo ti kọkọ bẹrẹ irinajo rẹ ko to pada si APC ko tun to pada si PDP ṣaaju idibo 2019. Saa kan lo lo lori ipo aarẹ ile aṣofin agba ko to fidi rẹmi ninu idibo to waye lẹyin. Ẹni ọdun mọkandinlọgọta ni Saraki ṣe to si jẹ onimọ nipa ilera ko to di oloṣelu. Sam Ohabunwa ni oludije ti ọjọ ori rẹ dagba julọ ṣikeji ninu awọn to n wa tikẹẹti PDP. Ipinlẹ Abia lo ti wa ni ilẹ Igbo Naijiria. O jẹ akọṣẹmọṣ apoogun to si tun jẹ oloṣelu. Saaju asiko yi o ti jẹ alaga igbimọ to n risi ọrọ aje Naijiria oun si ni alaga akọkọ fawọn ẹgbẹ awọn to peelo nkan ni Naijiria. Ohabunwa sọ pe oun ni iriri toun fi le sọ Naijiria di orileede ti yoo maa da pese ohun elo gbogbo to ba nilo. O ni Naijiria ti yapa bayi ati pe oun fẹ mu isọkan pada wa ki nkan si burẹkẹ fawọn eeyan orileede Naijiria. Tambuwal ti ṣe Gomina lẹẹmeeji ni ipinlẹ Sokoto. Ṣaaju lo jẹ ipo olori ile aṣojuṣofin Naijiria laarin ọdun 2011-2015. O gbero lati jẹ Aarẹ Naijiria lọdun 2019 ṣugbọn o kuna. Ninu awọn alatilẹyin rẹ nigba naa ni ọrẹ rẹ Gomina Nyesom Wike ipinlẹ Rivers. Amọ bayi ẹni ọdun mẹrindinlọgọta yi n wa tikẹẹti ipo aarẹ PDP pẹlu ọrẹ rẹ Wike. O ni erongba oun ni lati wa ojutu si gbogbo ipenija to n koju Naijiria, Gomina lọwọlọwọ ni Nyesom Wike j ni ipinlẹ Rivers. Agbẹjọro ni Wike to si di alaga ijọba ibilẹ Obio-Akpor lọdun 1999. Lọdun 2007 o riṣẹ gẹgẹ bi olori oṣiṣẹ ile ijọba fun Gomina Rotimi Amaechi Nigba ti yoo fi di 2011, Aarẹ tẹlẹ Goodluck Jonathan yan sipo Minisita feto ẹkọ. Lọdun 2015 lo di Gomina Rivers to si n ṣe saa keji rẹ lọwọ bayii. O ni ijọba oun gẹgẹ bi aarẹ yoo wa ojutu si gbogbo ipenija didari Naijiria toun yoo si sọ eto ọrọ aje ji pada. Gomina lọwọ bayi ni ipinlẹ Bauchi ni Bala Mohammede jẹ. Ṣaaju o ti jẹ Sẹnẹtọ laarin ọdun 2007-2010. Ni 2010 o di Minisita fun olu ilu Naijiria, FCT ti eleyi si tan irawọ rẹ soke gẹgẹ bi oloṣelu. Lọdun 2019 o jawe olubori ninu idibo to si wọle sipo Gomina Bauchi Ẹni ọdun mẹtalelọgọta yii sọ pe oun nigba pe oun le mu iyipada ba Naijiria Oloṣelu ati oniṣowo ni Peter Obi jẹ. O fi igba kan jẹ Gomina ni ipinlẹ Anambra to si lo saa meji laarin 2008-2018 Obi jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Grand Alliance (Apga) ki o to darapọ mọ PDP ni 2017. O tun jẹ eeyan kan to nimọ nipa eto ọrọ aje. Lọdun 2019 o jade gẹgẹ bi igbakeji Atiku Abubakar fun ipo aarẹ. Amọ lọdun 2022 o ni oun gaan loun f du ipo aarẹ. Ipese iṣẹ, mimu agbega ba eto ọrọ aje Naijiria ati eto ẹkọ ni afojusun Peter Obi to ba jẹ aarẹ Naijiria. Oṣokomọlẹ Gomina nigba kan ri ni Ayodele Fayose jẹ. O ṣe Gomina ni saa meji. Igba akọkọ ni laarin ọdun 2003 si 2006. O fipo silẹ ko to tun pada wa di Gomina ni igba ẹlẹẹkeji iyẹn laarin ọdun 2014-2018. Ẹni ọdun mejilelọgọta ni Fayose n ṣe. O ni oun ni iriri lati le mu iyipada ba Naijiria. Laarin ọjọ Kẹrin oṣu Kẹrin si ọjọ Kẹta oṣu Kẹfa lawọn ẹgbẹ oṣelu ni lati ṣeto idibo abẹnu kiwọn si yanju aawọ kankan to ba tẹyin rẹ wa. Eyi lọrọ to wa ninu ilana idibo ti ajọ eleto idibo INEC gbe jade. Wọn le lo ilana taarara, ẹlẹburu tabi ki wọn fẹnu ko lati yan oludije to ba wu wọn. Amọ ṣa INEC ni gbogbo awọn aṣoju ẹgbẹ lo gbọdọ buwọlu ki wọn sikopa ninu eto afẹnukoyan aṣoju yi taa mọ si "consensus." Gbogbo awọn aṣoju yi yoo si peju lati ipinlẹ mẹrindinlogoji si ibudo ti wọn ba yan lati ṣe ipade apero gbogboogbo ẹgbẹ wọn. A o maa fi orukọ awọn oludije mii sọwọ lori apilkọ yi bi wọn ba ti ṣe n yọju.Ẹ maa ba wa fkan ba eto naa bọ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61133831 |
3politics
| 2023 Presidency: Èsì Ààrẹ Buhari lórí ẹni tó jẹ́ ààyò rẹ̀ tí aráàlú ń bèrè nìyí | Ààrẹ Muhammadu Buhari ti jiyàn àhesọ ọ̀rọ̀ to wípé ó ní ààyò nínú gbogbo àwọn olóṣèlú tí wọ́n ti fi èròńgbà wọn léde láti di Ààrẹ Nàìjíríà ní kété tí òun bá fi àpèrè náà sílẹ̀ lọ́dún tó ń bọ̀. Buhari ní òun kò ní ẹnìkan lọ́kàn tí òun fẹ́ kó di Ààrẹ lẹ́yìn òun àyàfi ẹni tí àwọn ọmọ Nàìjíríà bá dìbò fún. Ó ní ẹni tí àwọn ọmọ Nàìjíríà bá ti yàn níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún tó ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò darí wọn fún ọdún mẹ́rin ni òun yóò fa ìṣàkóso orílẹ̀èdè yìí lé lọ́wọ́. Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejì, oṣù karùn-ún, ọdún 2022 ni Ààrẹ Muhammadu Buhari sọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn akọ̀ròyìn lẹ́yìn tó kírun yídì tán. $5.39 ni INEC yóò ná lórí olùdìbò kọ̀ọ̀kan lọ́dún 2023 Ọdaràn làwọn tó ń pè fún ìdìbò dípò 'Restructuring' tí a n béèrè- Iba Gani Adams OPC Mi ò tíì lè sọ bóyá ètò ìdìbò ọdún 2023 yóò wáyé - Adeboye Wo ìdí mẹ́ta tí káàdì ìdìbò rẹ̀ kò fi ní wúlò mọ́ Leke Adeboye àti ọ̀pọ̀ ọmọ ìjọ RCCG ń ṣèrántí ikú Dare Adeboye lẹ́yìn ọdún kan Ọlọ́run mi ló ní kí n bèèrè fún N310,000 lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ mi láti kó wọn lọ sí ọ̀run - Pásítọ̀ Noah Abraham Ní Bárékè Mambilla tó wà ní ìlú Abuja ni Ààrẹ Muhammadu Buhari ti kírun yídì ọdún ìtúnu àwẹ̀. Ààrẹ Buhari rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti jí gìrì sí iṣẹ́ wọn. Bákan náà ni Ààrẹ Muhammadu Buhari tún rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò orílẹ̀ èdè yìí láti túnbọ̀ jí gìrì sí ojúṣe wọn, kí wọ́n ri dájú pé ààbò tó péye wà fún tolórí tẹlẹ́mù Nàìjíríà. Ó rọ̀ wọ́n láti sa gbogbo ipá wọ́n láti ri pé wọ́n gbógunti ìpèníjà ètò ààbò tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ń kojú lọ́wọ́. Àwọn afurasí Fulani darandaran pa Atiku ní Ibarapa! 'Iye àwọn táa rí yọ láàyè, 23, àwọn tó kú sábẹ́ ilé alájà mẹ́ta ní Ibadan, Ebute Meta jẹ́ 10' Ọmọ Abiola Ajimobi, idris yóò di Aare Akogun Musulumi ìpínlẹ̀ Oyo tuntun Ṣé bí ọyàn rẹ ṣe tóbi tàbí kéré tó leè nípa lára ìpèsè omi ọyàn? Kí ni ìmọ̀ Sáyẹ́nsì sọ nípa àwọn ènìyàn tó ń bá ajá lòpọ̀? Ìwàdìí ìjìnlẹ̀ rèé Ó fi kun pé ó pọn dandan kí àyíká wà nínú ààbò tó péye pàápàá lásìkò òjò yìí kì àwọn àgbẹ̀ le padà sóko kí oúnjẹ le pọ̀ yanturu ní Nàìjíríà. Ààrẹ Buhari sọ síwájú pé gbogbo àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ ààbò tó fi mọ́ ti orí ilẹ̀, ojú omi àti ti òfurufú ló mọ ìpèníjà tí Nàìjíríà ń dojú kọ, tó sì ní iṣẹ́ wọn ni láti wá àwọn agbéṣùmọ̀mí náà rí, kí wọ́n sì pá wọ́n tán. Ṣaájú nínú ọ̀rọ̀ ìkíni kú ọdún tí Ààrẹ Buhari fi léde lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kìíní, oṣù karùn-ún ni ó ti tẹmpẹlẹmọ wí pé ìṣèjọba òun ní ìfarajìn sí fífi òpin sí àìsí ètò ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra. Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjà náà lè díẹ̀, tó sì ti ń lọ fún ọjọ́ pípẹ́, òun ní ìgbàgbọ́ wí pé dídùn ni ọsàn yóò so nígbẹ̀yìn. | 2023 Presidency: Èsì Ààrẹ Buhari lórí ẹni tó jẹ́ ààyò rẹ̀ tí aráàlú ń bèrè nìyí Ààrẹ Muhammadu Buhari ti jiyàn àhesọ ọ̀rọ̀ to wípé ó ní ààyò nínú gbogbo àwọn olóṣèlú tí wọ́n ti fi èròńgbà wọn léde láti di Ààrẹ Nàìjíríà ní kété tí òun bá fi àpèrè náà sílẹ̀ lọ́dún tó ń bọ̀. Buhari ní òun kò ní ẹnìkan lọ́kàn tí òun fẹ́ kó di Ààrẹ lẹ́yìn òun àyàfi ẹni tí àwọn ọmọ Nàìjíríà bá dìbò fún. Ó ní ẹni tí àwọn ọmọ Nàìjíríà bá ti yàn níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún tó ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò darí wọn fún ọdún mẹ́rin ni òun yóò fa ìṣàkóso orílẹ̀èdè yìí lé lọ́wọ́. Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejì, oṣù karùn-ún, ọdún 2022 ni Ààrẹ Muhammadu Buhari sọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn akọ̀ròyìn lẹ́yìn tó kírun yídì tán. $5.39 ni INEC yóò ná lórí olùdìbò kọ̀ọ̀kan lọ́dún 2023 Ọdaràn làwọn tó ń pè fún ìdìbò dípò 'Restructuring' tí a n béèrè- Iba Gani Adams OPC Mi ò tíì lè sọ bóyá ètò ìdìbò ọdún 2023 yóò wáyé - Adeboye Wo ìdí mẹ́ta tí káàdì ìdìbò rẹ̀ kò fi ní wúlò mọ́ Leke Adeboye àti ọ̀pọ̀ ọmọ ìjọ RCCG ń ṣèrántí ikú Dare Adeboye lẹ́yìn ọdún kan Ọlọ́run mi ló ní kí n bèèrè fún N310,000 lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ mi láti kó wọn lọ sí ọ̀run - Pásítọ̀ Noah Abraham Ní Bárékè Mambilla tó wà ní ìlú Abuja ni Ààrẹ Muhammadu Buhari ti kírun yídì ọdún ìtúnu àwẹ̀. Ààrẹ Buhari rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti jí gìrì sí iṣẹ́ wọn. Bákan náà ni Ààrẹ Muhammadu Buhari tún rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò orílẹ̀ èdè yìí láti túnbọ̀ jí gìrì sí ojúṣe wọn, kí wọ́n ri dájú pé ààbò tó péye wà fún tolórí tẹlẹ́mù Nàìjíríà. Ó rọ̀ wọ́n láti sa gbogbo ipá wọ́n láti ri pé wọ́n gbógunti ìpèníjà ètò ààbò tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ń kojú lọ́wọ́. Àwọn afurasí Fulani darandaran pa Atiku ní Ibarapa! 'Iye àwọn táa rí yọ láàyè, 23, àwọn tó kú sábẹ́ ilé alájà mẹ́ta ní Ibadan, Ebute Meta jẹ́ 10' Ọmọ Abiola Ajimobi, idris yóò di Aare Akogun Musulumi ìpínlẹ̀ Oyo tuntun Ṣé bí ọyàn rẹ ṣe tóbi tàbí kéré tó leè nípa lára ìpèsè omi ọyàn? Kí ni ìmọ̀ Sáyẹ́nsì sọ nípa àwọn ènìyàn tó ń bá ajá lòpọ̀? Ìwàdìí ìjìnlẹ̀ rèé Ó fi kun pé ó pọn dandan kí àyíká wà nínú ààbò tó péye pàápàá lásìkò òjò yìí kì àwọn àgbẹ̀ le padà sóko kí oúnjẹ le pọ̀ yanturu ní Nàìjíríà. Ààrẹ Buhari sọ síwájú pé gbogbo àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ ààbò tó fi mọ́ ti orí ilẹ̀, ojú omi àti ti òfurufú ló mọ ìpèníjà tí Nàìjíríà ń dojú kọ, tó sì ní iṣẹ́ wọn ni láti wá àwọn agbéṣùmọ̀mí náà rí, kí wọ́n sì pá wọ́n tán. Ṣaájú nínú ọ̀rọ̀ ìkíni kú ọdún tí Ààrẹ Buhari fi léde lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kìíní, oṣù karùn-ún ni ó ti tẹmpẹlẹmọ wí pé ìṣèjọba òun ní ìfarajìn sí fífi òpin sí àìsí ètò ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra. Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjà náà lè díẹ̀, tó sì ti ń lọ fún ọjọ́ pípẹ́, òun ní ìgbàgbọ́ wí pé dídùn ni ọsàn yóò so nígbẹ̀yìn. | https://www.bbc.com/yoruba/61303843 |
1entertainment
| Testimony Jaga sọ ohun tójú rẹ rí kó tó lè wo ara rẹ̀ láwòdúpẹ́ | "Kí n máa kọrin Ọlọ́run láàrín àwọn amugbó pé mi ju kí wọ́n pè mí sí ìsọjí ńla lọ". BBc Yoruba ba akọrin ẹ́mi ti ọpọlọpọ mọ si Testimony Jaga lalejo nile orin rẹ. Jaga kẹnu bọrọ, ko fẹ tan mọ tori itan igbesi aye rẹ ko to de ibi to yanju fọwọ tọ ni lọkan gan. "Ìdíle olórógún lórí mi yàn nígbà tí mo dé ayé. Ìyawó mẹ́fa, àwa ọmọ 27, láàrín wọn ni mo ti jáde". Jaga ni ipo kejilelogun loun wa ninu awọn ọmọ baba oun. O ni "ìyá mi kò rí mi bí lásìkò tó yẹ kí ó bi mi, Ọ̀tá mi tún kú lọ́jọ́ ìkómọ fún wákàtí mẹ́jọ". "Mo ti kó sọ́wọ́ Ọlọ́pàá lọ́pọ̀ ìgbà, SARS, Area G ...iya mi nikan lo maa n wa lẹyin mi ni gbogbo igba titi ti Ọlọrun fi ṣeyanu ko to di pe awọn oniroyin gbe mi saye". Ohun ti Jaga la kọja lo jẹ ko sọ fun Ọlọrun pe bi o ba le ko oun yọ ninu iṣoro, oun a sin in. | Testimony Jaga sọ ohun tójú rẹ rí kó tó lè wo ara rẹ̀ láwòdúpẹ́ "Kí n máa kọrin Ọlọ́run láàrín àwọn amugbó pé mi ju kí wọ́n pè mí sí ìsọjí ńla lọ". BBc Yoruba ba akọrin ẹ́mi ti ọpọlọpọ mọ si Testimony Jaga lalejo nile orin rẹ. Jaga kẹnu bọrọ, ko fẹ tan mọ tori itan igbesi aye rẹ ko to de ibi to yanju fọwọ tọ ni lọkan gan. "Ìdíle olórógún lórí mi yàn nígbà tí mo dé ayé. Ìyawó mẹ́fa, àwa ọmọ 27, láàrín wọn ni mo ti jáde". Jaga ni ipo kejilelogun loun wa ninu awọn ọmọ baba oun. O ni "ìyá mi kò rí mi bí lásìkò tó yẹ kí ó bi mi, Ọ̀tá mi tún kú lọ́jọ́ ìkómọ fún wákàtí mẹ́jọ". "Mo ti kó sọ́wọ́ Ọlọ́pàá lọ́pọ̀ ìgbà, SARS, Area G ...iya mi nikan lo maa n wa lẹyin mi ni gbogbo igba titi ti Ọlọrun fi ṣeyanu ko to di pe awọn oniroyin gbe mi saye". Ohun ti Jaga la kọja lo jẹ ko sọ fun Ọlọrun pe bi o ba le ko oun yọ ninu iṣoro, oun a sin in. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51353825 |
5sports
| Emmanuel Adebayor: Agbábọ́ọ̀lù Togo rántí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lásìkò AFCON 2010 | Ọjọ buruku eṣu gbomi mu, oni ọjọ kẹjọ oṣu kinni ọdun 2020 lo pe ọdun mẹwaa tawọn agbebọn kan kọlu awọn agbabọọlu ilẹ Afirika lorilẹede Angola. Awọn ti ori ko yọ ninu iṣẹlẹ naa, ninu eyi tawọn kan ti di ero ọrun, ṣe iranti bi iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ lapa ẹkun Cabinda lorilẹede Angola. Akọroyin BBC, Matthew Kenyon naa ṣe iranti bi ikọlu naa ṣe mu ẹmi awọn agbabọọlu orilẹede Togo meji lọ. Kenyon ni lẹyin tawọn agbebọn kọlu ọkọ tawọn ẹgbẹ agbabọọlu Togo wa ninu rẹ, loun ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu agbẹnusọ ikọ naa, tii ṣe Emmanuel Adebayor, to n ṣoju ikọ agbabọọlu Manchester City nigba naa. O ṣalaye pe, ti ibẹru-bojo ni Adebayor fi n sọ ohun to sẹlẹ ṣawọn agbabọọlu Togo, koda Adebayor sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo naa pe, ẹru ṣi n ba oun lẹyin tawọn akẹgbẹ rẹ meji ṣagbako iku ninu ikọlu naa. Junior Senaya to jẹ ọkan lara awọn agbabọọlu fikun ọrọ Adebayor pe, ninu ọkọ lawọn wa tawọn n gbọ orin, ṣadeedee lawọn bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn ninu igbo. ''Ka to wi, ka to fọ, wọn yinbọn pawọn akẹgbẹ wa ti a jọ wa ninu ọkọ, nibi ti gbogbo wa ti mọ pe ewu n bẹ loko longẹ niyẹn,'' Senaya lo woye bẹẹ. Kodjovi Obilale, to jẹ aṣọle nigba naa kan ṣadeedee ri pe oun ti fara gbọta, loju ẹsẹ lo rii pe ẹjẹ bẹrẹ si ni da lati ikun ati ẹsẹ oun mejeeji. Obiulale ni lẹsẹkẹsẹ loun bẹrẹ si ni ke pe ''ẹ gbami, ẹ gbami, ọta ibọn ti ba mi, mo fẹ ri ọmọbinrin ati ọmọkunrin mi, mi o fẹ ku sibi.'' Igbakeji akọnimọọgba fẹgbẹ agbabọọlu Togo, Amelete Abalo naa figbe ta pe ọta ibọn ba oun, Amelete pada ku lẹyin ti ọta ibọn ba a tan. Adebayor ranti pe, fun bi ọgbọn iṣẹju lawọn janduku naa fi n dabọn bo ọkọ tawọn wa ninu rẹ, lai le kuro loju kan naa. Adebayor ni iṣẹlẹ naa jẹ ọkan lara awọn manigbagbe iṣẹlẹ to buru ju to ṣẹlẹ s'oun laye. | Emmanuel Adebayor: Agbábọ́ọ̀lù Togo rántí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lásìkò AFCON 2010 Ọjọ buruku eṣu gbomi mu, oni ọjọ kẹjọ oṣu kinni ọdun 2020 lo pe ọdun mẹwaa tawọn agbebọn kan kọlu awọn agbabọọlu ilẹ Afirika lorilẹede Angola. Awọn ti ori ko yọ ninu iṣẹlẹ naa, ninu eyi tawọn kan ti di ero ọrun, ṣe iranti bi iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ lapa ẹkun Cabinda lorilẹede Angola. Akọroyin BBC, Matthew Kenyon naa ṣe iranti bi ikọlu naa ṣe mu ẹmi awọn agbabọọlu orilẹede Togo meji lọ. Kenyon ni lẹyin tawọn agbebọn kọlu ọkọ tawọn ẹgbẹ agbabọọlu Togo wa ninu rẹ, loun ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu agbẹnusọ ikọ naa, tii ṣe Emmanuel Adebayor, to n ṣoju ikọ agbabọọlu Manchester City nigba naa. O ṣalaye pe, ti ibẹru-bojo ni Adebayor fi n sọ ohun to sẹlẹ ṣawọn agbabọọlu Togo, koda Adebayor sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo naa pe, ẹru ṣi n ba oun lẹyin tawọn akẹgbẹ rẹ meji ṣagbako iku ninu ikọlu naa. Junior Senaya to jẹ ọkan lara awọn agbabọọlu fikun ọrọ Adebayor pe, ninu ọkọ lawọn wa tawọn n gbọ orin, ṣadeedee lawọn bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn ninu igbo. ''Ka to wi, ka to fọ, wọn yinbọn pawọn akẹgbẹ wa ti a jọ wa ninu ọkọ, nibi ti gbogbo wa ti mọ pe ewu n bẹ loko longẹ niyẹn,'' Senaya lo woye bẹẹ. Kodjovi Obilale, to jẹ aṣọle nigba naa kan ṣadeedee ri pe oun ti fara gbọta, loju ẹsẹ lo rii pe ẹjẹ bẹrẹ si ni da lati ikun ati ẹsẹ oun mejeeji. Obiulale ni lẹsẹkẹsẹ loun bẹrẹ si ni ke pe ''ẹ gbami, ẹ gbami, ọta ibọn ti ba mi, mo fẹ ri ọmọbinrin ati ọmọkunrin mi, mi o fẹ ku sibi.'' Igbakeji akọnimọọgba fẹgbẹ agbabọọlu Togo, Amelete Abalo naa figbe ta pe ọta ibọn ba oun, Amelete pada ku lẹyin ti ọta ibọn ba a tan. Adebayor ranti pe, fun bi ọgbọn iṣẹju lawọn janduku naa fi n dabọn bo ọkọ tawọn wa ninu rẹ, lai le kuro loju kan naa. Adebayor ni iṣẹlẹ naa jẹ ọkan lara awọn manigbagbe iṣẹlẹ to buru ju to ṣẹlẹ s'oun laye. | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-51036889 |
1entertainment
| Baba Ijesha: Ebun Oloyede ní àwọn ọmọ ẹgbẹ TAMPAN ní ẹgbẹ́ fòfin dè láti máṣe bá Iyabo Ojo àti Nkechi Blessing ṣiṣẹ́ papọ̀ | Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Ebun Oloyede, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Olaiya Igwe ti sọ pe, ẹgbẹ awọn ko lagbara lati fofin de Nkechi Blessing ati Iyabo Ojo lẹyin ti wọn ri awọn agba ẹgbẹ naa fin. Olaiya lo ṣiṣọ loju ọrọ naa lori eto kan to ti fọrọ jomitoro ọrọ pẹlu BBC Yoruba. Igwe ṣalaye pe niwọn igba ti awọn oṣere naa kii tii ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn, iyẹn TAMPAN, awọn ko le fofin de wọn lati ma ṣere mọ. Ṣugbọn o ṣalaye pe ẹgbẹ ọhun ti paṣẹ pe ẹnikẹni ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ko gbọdọ ba eyikeyi ninu Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing da iṣẹ pọ mọ fun saa yii. O ni "Oṣere tiata ni wọn, ṣugbọn wọn kii ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, nitori naa ẹgbẹ wa ko le fofin de awọn memeji." "Ṣugbọn iru emi ti mo n ba yin sọrọ yii atawọn ọmọ ẹgbẹ ti orukọ wọn wa ninu iwe ẹgbẹ wa, ni wọn fofin de lati mase ba Nkechi Blessing ati Iyabo Ojo ṣiṣẹ mọ." Ṣaaju ni Nkechi ati Iyabo ti kọkọ sọrọ kobakungbe si awọn agba ẹgbẹ TAMPAN loju opo Instagram wọn, lori awọn ọrọ kan to ti ṣẹlẹ ṣaaju, paapaa lori ọrọ baba Ijesha. Ẹwẹ, ni ti ijiya to wa fun awọn oṣẹre tiata Yoruba to ba tasẹ agẹrẹ, Olaiya sọ pe Aarẹ ẹgbẹ TAMPAN, Bola Amusan, ta tun mọ si Mr Latin, nikan lo le sọ irufẹ ijiya to yẹ fun wọn. Olaiya sọ pe awọn idanilẹkọ maa n waye ninu ẹgbẹ TAMPAN, nibi ti wọn ti maa n ba awọn oṣere sọrọ lori bo ṣe yẹ ki wọn ṣe maa ṣe lawujọ, ṣugbọn onikaluku ni yoo mọ bi yoo ṣe maa ko ara rẹ ni ijanu. Ni ti afojusun rẹ fun ọjọ iwaju, Olaiya sọ pe ere ti oun yoo ṣe kẹyin yoo milẹ titi, koda aye yoo gbọ, ọrun yoo mọ pẹlu. O ni yoo wu ohun ki sinima naa le wọ ori ẹrọ Ntflix, nibi ti awọn eeyan yoo ti le maa wo kaakiri agbaye, ati pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ere naa ni sinima ti oun yoo gbe jade kẹyin. Lẹyin naa lo gba awọn ololufẹ tiata Yoruba niyanju lati maṣe maa wo awọn aṣemaṣe awọn oṣere, ṣugbọn ki wọn maa wo awọn ere wọn lati kọgbọn ati fun oniruru awokọṣe rere. | Baba Ijesha: Ebun Oloyede ní àwọn ọmọ ẹgbẹ TAMPAN ní ẹgbẹ́ fòfin dè láti máṣe bá Iyabo Ojo àti Nkechi Blessing ṣiṣẹ́ papọ̀ Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Ebun Oloyede, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Olaiya Igwe ti sọ pe, ẹgbẹ awọn ko lagbara lati fofin de Nkechi Blessing ati Iyabo Ojo lẹyin ti wọn ri awọn agba ẹgbẹ naa fin. Olaiya lo ṣiṣọ loju ọrọ naa lori eto kan to ti fọrọ jomitoro ọrọ pẹlu BBC Yoruba. Igwe ṣalaye pe niwọn igba ti awọn oṣere naa kii tii ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn, iyẹn TAMPAN, awọn ko le fofin de wọn lati ma ṣere mọ. Ṣugbọn o ṣalaye pe ẹgbẹ ọhun ti paṣẹ pe ẹnikẹni ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ko gbọdọ ba eyikeyi ninu Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing da iṣẹ pọ mọ fun saa yii. O ni "Oṣere tiata ni wọn, ṣugbọn wọn kii ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, nitori naa ẹgbẹ wa ko le fofin de awọn memeji." "Ṣugbọn iru emi ti mo n ba yin sọrọ yii atawọn ọmọ ẹgbẹ ti orukọ wọn wa ninu iwe ẹgbẹ wa, ni wọn fofin de lati mase ba Nkechi Blessing ati Iyabo Ojo ṣiṣẹ mọ." Ṣaaju ni Nkechi ati Iyabo ti kọkọ sọrọ kobakungbe si awọn agba ẹgbẹ TAMPAN loju opo Instagram wọn, lori awọn ọrọ kan to ti ṣẹlẹ ṣaaju, paapaa lori ọrọ baba Ijesha. Ẹwẹ, ni ti ijiya to wa fun awọn oṣẹre tiata Yoruba to ba tasẹ agẹrẹ, Olaiya sọ pe Aarẹ ẹgbẹ TAMPAN, Bola Amusan, ta tun mọ si Mr Latin, nikan lo le sọ irufẹ ijiya to yẹ fun wọn. Olaiya sọ pe awọn idanilẹkọ maa n waye ninu ẹgbẹ TAMPAN, nibi ti wọn ti maa n ba awọn oṣere sọrọ lori bo ṣe yẹ ki wọn ṣe maa ṣe lawujọ, ṣugbọn onikaluku ni yoo mọ bi yoo ṣe maa ko ara rẹ ni ijanu. Ni ti afojusun rẹ fun ọjọ iwaju, Olaiya sọ pe ere ti oun yoo ṣe kẹyin yoo milẹ titi, koda aye yoo gbọ, ọrun yoo mọ pẹlu. O ni yoo wu ohun ki sinima naa le wọ ori ẹrọ Ntflix, nibi ti awọn eeyan yoo ti le maa wo kaakiri agbaye, ati pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ere naa ni sinima ti oun yoo gbe jade kẹyin. Lẹyin naa lo gba awọn ololufẹ tiata Yoruba niyanju lati maṣe maa wo awọn aṣemaṣe awọn oṣere, ṣugbọn ki wọn maa wo awọn ere wọn lati kọgbọn ati fun oniruru awokọṣe rere. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57655030 |
1entertainment
| Live Eviction show BBNaija 2021 :WhiteMoney ló gbé igbá orókè nínú ètò ẹlẹ́gbọ̀n ọ́n àgbà ọdún 2021 | Ètò ẹlẹ́gbọ́n àgbà ọdún 2021 ti wa o si ti parí lẹyin ọṣẹ mẹwaa tí gbogbo àwọn ọdọ ti kojú mọ ètò náàs lóri amóhúnmáwòrán. Whitemoney ni oludije to gbegba oroke ninu idije BBNaija eyi to jẹ ipele ikẹfa iru rẹ. Ibeere ti ọpọ n beere ni pe ta ni Whitemoney naa? Ta ni Whitemoney to gba aadọrun un miliọnu lọ ninu idije BB Naija? Orukọ abisọ whitemoney ni Hazel Oyeye Onou. Oun lo figagbaga pẹlu awọn to le ni ogun ninu ile ẹlẹgbọn ọn agba ti ọdun 2021 ti wọn pe ni 'shine Ya Eye' Whitemoney jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn. Omo bibi ipinlẹ enugu ni ila oorun guusu Naijiria ni. O jẹ oniṣowo bata lati ilẹ okeere ati ni Naijiria. O ti dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ Naijira fun atilẹyin wọn fun oun. Sùgbọ́n lẹ́yìn ò rẹyin Hazel Oyeze Onou ti gbogbo eniyan mọ si Whitemoney ló gbegba oroke fun ti eto ọdun yii ti Roseline Omokhoa Afije ti gbogbo eniyan mọ si Liquorose si gba ipo keji. Whitemoney da oju awọn ọmọ ile ogun to u bolẹ lati gbegba oroke ti ọdun yii, o jẹ́ ẹni kẹfa ti yuoo jawee olubori ninu eto naa lati igba ti o ti bẹrẹ. Ni bayii o ti darapọ mọ awọn to ti gbegba oroke eto nas saaju bi: Katung Aduwakwey to gba ti saa akọkọ eto naa, lọdun 2006, Efe Ejeba (2017), Miracle Ikechukwu (2018) ,Mercy Eke (2019), àti Laycon lọdun 2020. Whitemoney jẹ onisowo ti o si ti jẹ ki gbogbo eniyan mọ lati ibẹrẹ pe, owo ni oun yoo ṣe. Whitemoney lo gbe igbá orókè nínú ètò ẹlẹ́gbọ̀n ọ́n àgbà ọdún 2021 Ẹbun aadọrun mílọnu naa ni owo ọgbọn miliọnu naira, Owo ninu apo Abeg digital ati bitcoin lati ọwọ Patricia, ile oni yara meji, Mọto ayọkẹlẹ igbalode ati irina ajo lo si Dubai. Nínú ètò ilé ẹlẹgbọn àgbà tó n lọ lọ́wọ́, àwọn mẹ́rin ni wọ́n ti kíuro nínú ilé báyiì i ìjàkadi si kù sí ààrín White Money ati Liquorose Tani yóò gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́rún Nàìrà lọ le. Eto ti alẹ́ yìí kọ́ka ran Emmanuel lọ ile, ti ọ̀pọ̀ sì n sọ pé, nǹkan ti o tọ ni ati pe, ore-ọfẹ ni Emmanuel ni lati wa ninu ile élégbọn agba titi di asiko tí o lọ. Eto sin nlọ lọwọ sugbọn a ko ti mọ ẹni ti yoo gba ẹgbun tabua yii lọle Lasiko ti Pere n lọ o ní ọ̀rọ̀ kan ti òn yoo sọ ni pe oun nifẹ Maria Awọn ololufẹ ere idaraya ori tẹlifisọn ti wọn pe orukọ rẹ ni ''Big Brother Naija'' n foju sọna fun opin ere naa ti yoo waye ni Ọjọ Aiku, Ọjọ Kẹta, Osu Kẹwaa, ọdun 2021. Oni to jẹ opin Big Brother Naija naa ni o pe ọjọ mejilelaadọrin ti awọn ọmọ ile Big Brother ti lo ninu ile naa ni saa yii. Amọ, eniyan kan ninu awọn oludije mẹfa to lu ninu awọn mẹrindinlọgbọn to bẹrẹ lati ibẹrẹ ni yoo gbe igba oroke ni oni. Awọn mẹfa to ku naa ni Whitemoney, Liquorose, Pere, Cross, Angel ati Emmanuel, bio tilẹ jẹpe oju wa lara Whitemoney ati Liquorose gẹgẹ bi ẹni ti yoo yege julọ nitori bi awọn oluworan ṣe fẹran wọn si. Ere idaraya lori ẹrọ tẹlifisọn ni Big Brother Naija, ti awọn ileeṣẹ amohunmaworan kan si n ṣe agbatẹru fun un. Ohun ti o ma n ṣẹlẹ ni Big Brother ni pe awọn eniyan yoo jọ gbepọ ninu ile kan naa fun ọjọ mejilelaadọrin, lai ni anfaani si ohun to n ṣẹlẹ ni agbaye, to fi mọ aini anafaani si ẹrọ ilewọ wọn. Awọn alakoso eto naa ma n lo ẹrọ amọhun ati amaworan lati fi tọ paṣẹ awọn ọmọ ile naa fun wakati merinlelogun ọjọ lai yọ ẹnikẹni silẹ. Bakan naa ni Big Brother ma n gbe iṣẹ fun wọn lati ṣe, eleyii to ni owo lori. Ọṣọọṣẹ si ni wọn ma n dinku lẹyin ti awọn ara ile ba dibo yan ẹni ti wọn fẹ ko kuro ninu ile ni ọṣẹ naa. Ni oni to jẹ ọjọ to gbẹyin naa ni awọn eniyan yoo tun dibo fun ẹni ti wọn fẹ ko gbe igba oroke ninu eto naa. Gẹgẹ bi awọn adari eto naa ṣe sọ, Ọjọ Aiku, Ọjọ Kẹta, Osu Kẹwaa, ọdun 2021 ni yoo pari. Awọn eniyan si le wo aṣekagba naa ni ori ikanni ayelujara Dstv channel 198, GOtv channel 29 (Channel 129 for Ghana and Channel 329 for Uganda). Aago meje asalẹ oni ni yoo waye ni ori ikanni BBNaija ti awọn eniyan ti n wo. Ebuka Obi -Uchendu ni yoo tun se atọkun eto naa loni pẹlu awọn amuludun olorin lati orilẹede Naijiria ti yoo ma a da awọn eniyan ni ara ya. Bi o tilẹ jẹpe wọn ko i tii fi idi rẹ mulẹ, o ṣeeṣe ki awọn ọmọ ile Big Brother Naija ti wọn ti le lọ pẹjọ pọ si ibi aṣekagba naa loni. Ẹnikẹni to ba gbegba oroke ninu awọn mẹfa to ku to n dije loni yoo gba aadọrun miliọnu naira, N90M lo si ile fi ṣe ara rindin. Awọn ohun to wa ninu aadọrun miliọnu naira naa ni ọgbọn miliọnu naira ni iye owo amudani, ti wọn yoo tun ni owo ẹrọ ayelujara Abeg digital wallet, bitcoins lati ọwọ onigbọwọ wọn Patricia. Bakan naa ni ẹni ọhun yoo gba ẹbun ile olojule meji (two-bedroom apartment) lati ọwọ RevolutionPlus Property. To fi mọ ọkọ ayọkẹlẹ a top of di range SUV ti Innoson Motors ti orilẹede Naijiria ṣe. Ko tan si bẹ, ẹni to ba jawe olubori yoo tun rin irinajo igbafẹ fun eniyan meji, eleyii ti Travelbeta yoo ṣe agbatẹru rẹ. Ohun márùn ún tí ejò ń jẹ Ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ikọlu wáyé láwọn ọgbà ẹwọn Nàìjíríà Àrà kengé! Alábòyun ṣe iṣẹ́ abẹ pẹ̀lú abẹfẹ́lẹ́, ó gbé ọmọ jádé nínú ara a rẹ̀ "Ó yẹ kí ìjọba máa fún wa ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tí oyún bá bàjẹ́ mọ́ wa lára" Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun ti pàsẹ pé ki adarí OPIC tẹ́lẹ̀ri dá #40 miliọ̀nù padà | Live Eviction show BBNaija 2021 :WhiteMoney ló gbé igbá orókè nínú ètò ẹlẹ́gbọ̀n ọ́n àgbà ọdún 2021 Ètò ẹlẹ́gbọ́n àgbà ọdún 2021 ti wa o si ti parí lẹyin ọṣẹ mẹwaa tí gbogbo àwọn ọdọ ti kojú mọ ètò náàs lóri amóhúnmáwòrán. Whitemoney ni oludije to gbegba oroke ninu idije BBNaija eyi to jẹ ipele ikẹfa iru rẹ. Ibeere ti ọpọ n beere ni pe ta ni Whitemoney naa? Ta ni Whitemoney to gba aadọrun un miliọnu lọ ninu idije BB Naija? Orukọ abisọ whitemoney ni Hazel Oyeye Onou. Oun lo figagbaga pẹlu awọn to le ni ogun ninu ile ẹlẹgbọn ọn agba ti ọdun 2021 ti wọn pe ni 'shine Ya Eye' Whitemoney jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn. Omo bibi ipinlẹ enugu ni ila oorun guusu Naijiria ni. O jẹ oniṣowo bata lati ilẹ okeere ati ni Naijiria. O ti dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ Naijira fun atilẹyin wọn fun oun. Sùgbọ́n lẹ́yìn ò rẹyin Hazel Oyeze Onou ti gbogbo eniyan mọ si Whitemoney ló gbegba oroke fun ti eto ọdun yii ti Roseline Omokhoa Afije ti gbogbo eniyan mọ si Liquorose si gba ipo keji. Whitemoney da oju awọn ọmọ ile ogun to u bolẹ lati gbegba oroke ti ọdun yii, o jẹ́ ẹni kẹfa ti yuoo jawee olubori ninu eto naa lati igba ti o ti bẹrẹ. Ni bayii o ti darapọ mọ awọn to ti gbegba oroke eto nas saaju bi: Katung Aduwakwey to gba ti saa akọkọ eto naa, lọdun 2006, Efe Ejeba (2017), Miracle Ikechukwu (2018) ,Mercy Eke (2019), àti Laycon lọdun 2020. Whitemoney jẹ onisowo ti o si ti jẹ ki gbogbo eniyan mọ lati ibẹrẹ pe, owo ni oun yoo ṣe. Whitemoney lo gbe igbá orókè nínú ètò ẹlẹ́gbọ̀n ọ́n àgbà ọdún 2021 Ẹbun aadọrun mílọnu naa ni owo ọgbọn miliọnu naira, Owo ninu apo Abeg digital ati bitcoin lati ọwọ Patricia, ile oni yara meji, Mọto ayọkẹlẹ igbalode ati irina ajo lo si Dubai. Nínú ètò ilé ẹlẹgbọn àgbà tó n lọ lọ́wọ́, àwọn mẹ́rin ni wọ́n ti kíuro nínú ilé báyiì i ìjàkadi si kù sí ààrín White Money ati Liquorose Tani yóò gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́rún Nàìrà lọ le. Eto ti alẹ́ yìí kọ́ka ran Emmanuel lọ ile, ti ọ̀pọ̀ sì n sọ pé, nǹkan ti o tọ ni ati pe, ore-ọfẹ ni Emmanuel ni lati wa ninu ile élégbọn agba titi di asiko tí o lọ. Eto sin nlọ lọwọ sugbọn a ko ti mọ ẹni ti yoo gba ẹgbun tabua yii lọle Lasiko ti Pere n lọ o ní ọ̀rọ̀ kan ti òn yoo sọ ni pe oun nifẹ Maria Awọn ololufẹ ere idaraya ori tẹlifisọn ti wọn pe orukọ rẹ ni ''Big Brother Naija'' n foju sọna fun opin ere naa ti yoo waye ni Ọjọ Aiku, Ọjọ Kẹta, Osu Kẹwaa, ọdun 2021. Oni to jẹ opin Big Brother Naija naa ni o pe ọjọ mejilelaadọrin ti awọn ọmọ ile Big Brother ti lo ninu ile naa ni saa yii. Amọ, eniyan kan ninu awọn oludije mẹfa to lu ninu awọn mẹrindinlọgbọn to bẹrẹ lati ibẹrẹ ni yoo gbe igba oroke ni oni. Awọn mẹfa to ku naa ni Whitemoney, Liquorose, Pere, Cross, Angel ati Emmanuel, bio tilẹ jẹpe oju wa lara Whitemoney ati Liquorose gẹgẹ bi ẹni ti yoo yege julọ nitori bi awọn oluworan ṣe fẹran wọn si. Ere idaraya lori ẹrọ tẹlifisọn ni Big Brother Naija, ti awọn ileeṣẹ amohunmaworan kan si n ṣe agbatẹru fun un. Ohun ti o ma n ṣẹlẹ ni Big Brother ni pe awọn eniyan yoo jọ gbepọ ninu ile kan naa fun ọjọ mejilelaadọrin, lai ni anfaani si ohun to n ṣẹlẹ ni agbaye, to fi mọ aini anafaani si ẹrọ ilewọ wọn. Awọn alakoso eto naa ma n lo ẹrọ amọhun ati amaworan lati fi tọ paṣẹ awọn ọmọ ile naa fun wakati merinlelogun ọjọ lai yọ ẹnikẹni silẹ. Bakan naa ni Big Brother ma n gbe iṣẹ fun wọn lati ṣe, eleyii to ni owo lori. Ọṣọọṣẹ si ni wọn ma n dinku lẹyin ti awọn ara ile ba dibo yan ẹni ti wọn fẹ ko kuro ninu ile ni ọṣẹ naa. Ni oni to jẹ ọjọ to gbẹyin naa ni awọn eniyan yoo tun dibo fun ẹni ti wọn fẹ ko gbe igba oroke ninu eto naa. Gẹgẹ bi awọn adari eto naa ṣe sọ, Ọjọ Aiku, Ọjọ Kẹta, Osu Kẹwaa, ọdun 2021 ni yoo pari. Awọn eniyan si le wo aṣekagba naa ni ori ikanni ayelujara Dstv channel 198, GOtv channel 29 (Channel 129 for Ghana and Channel 329 for Uganda). Aago meje asalẹ oni ni yoo waye ni ori ikanni BBNaija ti awọn eniyan ti n wo. Ebuka Obi -Uchendu ni yoo tun se atọkun eto naa loni pẹlu awọn amuludun olorin lati orilẹede Naijiria ti yoo ma a da awọn eniyan ni ara ya. Bi o tilẹ jẹpe wọn ko i tii fi idi rẹ mulẹ, o ṣeeṣe ki awọn ọmọ ile Big Brother Naija ti wọn ti le lọ pẹjọ pọ si ibi aṣekagba naa loni. Ẹnikẹni to ba gbegba oroke ninu awọn mẹfa to ku to n dije loni yoo gba aadọrun miliọnu naira, N90M lo si ile fi ṣe ara rindin. Awọn ohun to wa ninu aadọrun miliọnu naira naa ni ọgbọn miliọnu naira ni iye owo amudani, ti wọn yoo tun ni owo ẹrọ ayelujara Abeg digital wallet, bitcoins lati ọwọ onigbọwọ wọn Patricia. Bakan naa ni ẹni ọhun yoo gba ẹbun ile olojule meji (two-bedroom apartment) lati ọwọ RevolutionPlus Property. To fi mọ ọkọ ayọkẹlẹ a top of di range SUV ti Innoson Motors ti orilẹede Naijiria ṣe. Ko tan si bẹ, ẹni to ba jawe olubori yoo tun rin irinajo igbafẹ fun eniyan meji, eleyii ti Travelbeta yoo ṣe agbatẹru rẹ. Ohun márùn ún tí ejò ń jẹ Ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ikọlu wáyé láwọn ọgbà ẹwọn Nàìjíríà Àrà kengé! Alábòyun ṣe iṣẹ́ abẹ pẹ̀lú abẹfẹ́lẹ́, ó gbé ọmọ jádé nínú ara a rẹ̀ "Ó yẹ kí ìjọba máa fún wa ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tí oyún bá bàjẹ́ mọ́ wa lára" Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun ti pàsẹ pé ki adarí OPIC tẹ́lẹ̀ri dá #40 miliọ̀nù padà | https://www.bbc.com/yoruba/media-58778451 |
1entertainment
| Yomi Fabiyi: Kò bójú mu bí ẹgbẹ́ TAMPAN ṣe dá mí dúró torí sinimá Oko Iyabo, màá pe ẹjọ́ | Gbajumọ oserekùnrin, Yomi Fabiyi, ti ke si ẹgbẹ awọn oṣere, TAMPAN, lati pa orúkọ oun rẹ kuro ninu akọsilẹ awọn osere ti wọn fun niwe lọ rọọkun nile na tabi kuro ninu ẹgbẹ naa. Fabiyi sọ pe oun kii ṣe ọmọ ẹgbẹ naa, nitori naa ni àṣẹ ti wọn pa ko ṣe le fidi mulẹ. O ni oun ka lẹta kan ti wọn fi pe oun si ipade alaafia ninu oṣu Keje, sugbọn àṣírí pada tu si oun lọwọ pe nkan mii ni wọn fẹ sọ. Oṣu Keje ni ẹgbẹ TAMPAN fi ikede sita pe awọn da Yomi Fabiyi duro, ti wọn si ni ko lọ rọọkun nile na kuro ninu ẹgbẹ ọhun. Igbesẹ yii waye nitori sinima Oko Iyabo ti Yomi Fabiyi gbé jade, eyi ti ọpọlọpọ tọka si pe o dá lori ẹjọ ẹsun ifipabanilopọ ti oserekunrin, Baba Ijesha n jẹ lọwọ. Wọn ni o tako ofin ati ilana iṣẹ tiata lati lo orúkọ, akọsilẹ tabi iṣẹlẹ nipa ẹnikẹni, ninu sinima lai jẹ pe ẹni naa fi àṣẹ si i. Yatọ si igbesẹ ẹgbẹ TAMPAN, ile ẹjọ tun pasẹ pe wọn ko gbọdọ safihan sinima naa ni ibikibi lasiko yii. Ọgbẹni Fabiyi sọ pe ti ẹni ti kii ṣe akọṣẹmọṣẹ oṣere gan-an ba wo sinima Oko Iyabo, yoo ri pe oun ko si lara ẹni ti wọn fi ẹ̀tọ́ rẹ dùn. O ni koda, gbogbo awọn ti wọn sọ pe oun fi sinima naa bá wi ni oun bọ̀wọ̀ fun pẹlu bi oun ko ṣe lo gbogbo orúkọ ti wọn n jẹ, aworan tabi ohùn wọn. O ni "pẹlu nkan to ṣẹlẹ yii, ko buru ti mo ba sọ pe TAMPAN lo mu ki ijọba gbogun ti sinima mi, emi gan-an-gan, ati orisun ọrọ aje mi." "Idi ni pe ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ni iṣẹ pari lori Oko Iyabo, saaju ki awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ to o pari iyansẹlodi wọn." O ni ti akoko ba to, oun yoo fi ilana ofin gbèjà ara oun nitori pe oun ko bẹru eniyan kankan, a fi Ọlọ́run. Lori ofin ti ile ẹjọ fi de sinima naa, Oko Iyabo, Ọgbẹni Fabiyi sọ pe oun yoo tẹle ofin naa bo se yẹ. O sọ pe sinima oun kii ṣe nipa ẹjọ ifipabanilopọ ti Baba Ijesha n jẹ rara. " Nitori naa, gbigbogun ti sinima Oko Iyabo ko bojumu". | Yomi Fabiyi: Kò bójú mu bí ẹgbẹ́ TAMPAN ṣe dá mí dúró torí sinimá Oko Iyabo, màá pe ẹjọ́ Gbajumọ oserekùnrin, Yomi Fabiyi, ti ke si ẹgbẹ awọn oṣere, TAMPAN, lati pa orúkọ oun rẹ kuro ninu akọsilẹ awọn osere ti wọn fun niwe lọ rọọkun nile na tabi kuro ninu ẹgbẹ naa. Fabiyi sọ pe oun kii ṣe ọmọ ẹgbẹ naa, nitori naa ni àṣẹ ti wọn pa ko ṣe le fidi mulẹ. O ni oun ka lẹta kan ti wọn fi pe oun si ipade alaafia ninu oṣu Keje, sugbọn àṣírí pada tu si oun lọwọ pe nkan mii ni wọn fẹ sọ. Oṣu Keje ni ẹgbẹ TAMPAN fi ikede sita pe awọn da Yomi Fabiyi duro, ti wọn si ni ko lọ rọọkun nile na kuro ninu ẹgbẹ ọhun. Igbesẹ yii waye nitori sinima Oko Iyabo ti Yomi Fabiyi gbé jade, eyi ti ọpọlọpọ tọka si pe o dá lori ẹjọ ẹsun ifipabanilopọ ti oserekunrin, Baba Ijesha n jẹ lọwọ. Wọn ni o tako ofin ati ilana iṣẹ tiata lati lo orúkọ, akọsilẹ tabi iṣẹlẹ nipa ẹnikẹni, ninu sinima lai jẹ pe ẹni naa fi àṣẹ si i. Yatọ si igbesẹ ẹgbẹ TAMPAN, ile ẹjọ tun pasẹ pe wọn ko gbọdọ safihan sinima naa ni ibikibi lasiko yii. Ọgbẹni Fabiyi sọ pe ti ẹni ti kii ṣe akọṣẹmọṣẹ oṣere gan-an ba wo sinima Oko Iyabo, yoo ri pe oun ko si lara ẹni ti wọn fi ẹ̀tọ́ rẹ dùn. O ni koda, gbogbo awọn ti wọn sọ pe oun fi sinima naa bá wi ni oun bọ̀wọ̀ fun pẹlu bi oun ko ṣe lo gbogbo orúkọ ti wọn n jẹ, aworan tabi ohùn wọn. O ni "pẹlu nkan to ṣẹlẹ yii, ko buru ti mo ba sọ pe TAMPAN lo mu ki ijọba gbogun ti sinima mi, emi gan-an-gan, ati orisun ọrọ aje mi." "Idi ni pe ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ni iṣẹ pari lori Oko Iyabo, saaju ki awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ to o pari iyansẹlodi wọn." O ni ti akoko ba to, oun yoo fi ilana ofin gbèjà ara oun nitori pe oun ko bẹru eniyan kankan, a fi Ọlọ́run. Lori ofin ti ile ẹjọ fi de sinima naa, Oko Iyabo, Ọgbẹni Fabiyi sọ pe oun yoo tẹle ofin naa bo se yẹ. O sọ pe sinima oun kii ṣe nipa ẹjọ ifipabanilopọ ti Baba Ijesha n jẹ rara. " Nitori naa, gbigbogun ti sinima Oko Iyabo ko bojumu". | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-59130423 |
4religion
| Sammie Okposo: Torí mo bá obìnrin kan ní àjọṣepọ̀ l‘Amẹ́ríkà, mó ń wá ojú Ọlọ́run | Se ni ori ayelujara n gbona fẹlifẹli nipa bi gbajugbaja ojisẹ Ọlọrun ati akọrin ẹmi kan se jẹwọ iwa agbere to hu lasiko to rinrinajo lọ silẹ okeere. Akọrin ẹmi naa, Sammie Okposo lo tọrọ aforijin naa ninu iwe kan to kọ sawọn ọ̀rẹ́ ati ololufẹ rẹ eyi to ti lu ori ayelujara pa. Se ni ẹnu si n ya ọpọ eeyan nipa igbesẹ ẹni ẹmi naa, paapaa lori iwe to kọ sita nipa isẹlẹ naa. Oniruuru eeyan lo ti wa n sọ ero rẹ nipa isẹlẹ naa lori ayelujara, ti iroyin kan tiẹ ni obinrin ara Amẹrika naa ti loyun fun bi o tilẹ jẹ pe a ko le fidi eyi mulẹ. Okposo salaye pe ni opin ọdun to kọja 2021, ni oun tẹkọ leti rinrin ajo lọ silẹ Amẹrika, ti oun si yan obinrin kan ni ọrẹ. O ni lootọ ni oun mọ pe igbesẹ naa ko tọna, ti ko si ba ifẹ Ọlọrun mu gẹgẹ bi akọrin ẹmi ati pe oun ti se igbeyawo. Koda, oju n ti oun, ti oun si kabamọ iwa pansaga ti oun hu yii ati irora nla ti igbesẹ naa ti mu ba iyawo oun, Ozioma, idile oun ati oun gan alara. Ninu lẹta iforijin naa ni Sammie Okposo ti wa kede pe nibayi ti oun ti n wa ọna lati rin ni alaafia pẹlu Ọlọrun, oun si n tọrọ aforijin siwaju. Okposo ni "Mo ti da ara mi duro na kuro ninu gbogbo awọn isẹ to jẹ mọ ti iransẹ Ọlọrun titi ti maa fi ni idapada tootọ. Eyi ni igbesẹ to tọna niwaju Ọlọrun, mo si jẹ Ọlọrun ati awọn eeyan ni gbese yii." Akọrin ẹmi naa wa sọ fun Ozioma aya rẹ pe oun kabamọ pupọ pe oun ko ojuti ba, ti oun si da igbagbọ ati igbẹkẹle to ni ninu oun. "Idarijin rẹ se pataki fun mi lori iwa ijakulẹ ti mo hu, mo si gbadura pe titi gbogbo ọjọ aye mi ni maa fi maa wa ọna lati tun gbe igbagbọ ati igbẹkẹle naa ro." Sammie Okposo wa tun tọrọ aforijin ninu lẹta naa, lọwọ awọn baba ati iya rẹ ninu igbagbọ, to fi mọ awọn ojisẹ ihinrere fun iwa aimọra to hu naa. O ni oun kabamọ pupọ nipa ihuwasi oun naa pẹlu afikun pe ti kii ba se igbagbọ wọn pe Ọlọrun lo pe oun si isẹ iransẹ, oun ko ba ti si mọ. O tun wa rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ ijọ rẹ atawọn eeyan to n tẹle oun lẹyin lai mọ oun ni ojukoroju pe oun n tọrọ aforijin pe oun ja wọn kulẹ. Bakan naa lo ni oun kabamọ nipa irora ọkan ti oun ti le mu ba wọn amọ ki wọn tubọ maa gbadura fun oun ni. Ọgbọnjọ osu Karun ọdun 1971 ni wọn bi Sammie Okposo tii se gbajugbaja akọrin ẹmi ati aluduuru. Ọdun 2004 lo kọkọ gbe awo orin sita amọ o ti dara pọ mọ ọpọ olorin ẹmi miran lati se awo orin to gbajumọ sita. Akọrin ẹmi naa ti sere kaakiri awọn orilẹede lagbaye to fi mọ Yuroopu, Amẹrika ati Gẹẹsi. Awo orin ti Okposo gbe jade gbẹyin lọdun 2018 lo pe akọle rẹ ni The Statement, to si ti gba ami ẹyẹ jakejado agbaye. | Sammie Okposo: Torí mo bá obìnrin kan ní àjọṣepọ̀ l‘Amẹ́ríkà, mó ń wá ojú Ọlọ́run Se ni ori ayelujara n gbona fẹlifẹli nipa bi gbajugbaja ojisẹ Ọlọrun ati akọrin ẹmi kan se jẹwọ iwa agbere to hu lasiko to rinrinajo lọ silẹ okeere. Akọrin ẹmi naa, Sammie Okposo lo tọrọ aforijin naa ninu iwe kan to kọ sawọn ọ̀rẹ́ ati ololufẹ rẹ eyi to ti lu ori ayelujara pa. Se ni ẹnu si n ya ọpọ eeyan nipa igbesẹ ẹni ẹmi naa, paapaa lori iwe to kọ sita nipa isẹlẹ naa. Oniruuru eeyan lo ti wa n sọ ero rẹ nipa isẹlẹ naa lori ayelujara, ti iroyin kan tiẹ ni obinrin ara Amẹrika naa ti loyun fun bi o tilẹ jẹ pe a ko le fidi eyi mulẹ. Okposo salaye pe ni opin ọdun to kọja 2021, ni oun tẹkọ leti rinrin ajo lọ silẹ Amẹrika, ti oun si yan obinrin kan ni ọrẹ. O ni lootọ ni oun mọ pe igbesẹ naa ko tọna, ti ko si ba ifẹ Ọlọrun mu gẹgẹ bi akọrin ẹmi ati pe oun ti se igbeyawo. Koda, oju n ti oun, ti oun si kabamọ iwa pansaga ti oun hu yii ati irora nla ti igbesẹ naa ti mu ba iyawo oun, Ozioma, idile oun ati oun gan alara. Ninu lẹta iforijin naa ni Sammie Okposo ti wa kede pe nibayi ti oun ti n wa ọna lati rin ni alaafia pẹlu Ọlọrun, oun si n tọrọ aforijin siwaju. Okposo ni "Mo ti da ara mi duro na kuro ninu gbogbo awọn isẹ to jẹ mọ ti iransẹ Ọlọrun titi ti maa fi ni idapada tootọ. Eyi ni igbesẹ to tọna niwaju Ọlọrun, mo si jẹ Ọlọrun ati awọn eeyan ni gbese yii." Akọrin ẹmi naa wa sọ fun Ozioma aya rẹ pe oun kabamọ pupọ pe oun ko ojuti ba, ti oun si da igbagbọ ati igbẹkẹle to ni ninu oun. "Idarijin rẹ se pataki fun mi lori iwa ijakulẹ ti mo hu, mo si gbadura pe titi gbogbo ọjọ aye mi ni maa fi maa wa ọna lati tun gbe igbagbọ ati igbẹkẹle naa ro." Sammie Okposo wa tun tọrọ aforijin ninu lẹta naa, lọwọ awọn baba ati iya rẹ ninu igbagbọ, to fi mọ awọn ojisẹ ihinrere fun iwa aimọra to hu naa. O ni oun kabamọ pupọ nipa ihuwasi oun naa pẹlu afikun pe ti kii ba se igbagbọ wọn pe Ọlọrun lo pe oun si isẹ iransẹ, oun ko ba ti si mọ. O tun wa rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ ijọ rẹ atawọn eeyan to n tẹle oun lẹyin lai mọ oun ni ojukoroju pe oun n tọrọ aforijin pe oun ja wọn kulẹ. Bakan naa lo ni oun kabamọ nipa irora ọkan ti oun ti le mu ba wọn amọ ki wọn tubọ maa gbadura fun oun ni. Ọgbọnjọ osu Karun ọdun 1971 ni wọn bi Sammie Okposo tii se gbajugbaja akọrin ẹmi ati aluduuru. Ọdun 2004 lo kọkọ gbe awo orin sita amọ o ti dara pọ mọ ọpọ olorin ẹmi miran lati se awo orin to gbajumọ sita. Akọrin ẹmi naa ti sere kaakiri awọn orilẹede lagbaye to fi mọ Yuroopu, Amẹrika ati Gẹẹsi. Awo orin ti Okposo gbe jade gbẹyin lọdun 2018 lo pe akọle rẹ ni The Statement, to si ti gba ami ẹyẹ jakejado agbaye. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60125549 |
1entertainment
| Dudu Heritage Kò sí ń nǹkan tí ó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ, Bimbo Oshin kọ ọrọ ìdárò lẹyin ikú ọkọ rẹ tó d'oloogbe | Gbajúgbajà òṣèré tíátà Bimbo Oshin tí padà sí ojú òpó ikansiraẹni instagram lẹ́yìn oṣù diẹ tó o ti n sọfọ ikú ọkọ rẹ Dudu Heritage Ọkọ rẹ to kú ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹsàn-án ọdún 2021 tí ọ̀pọ̀ àwọn alabasisẹpọ rẹ sì jáde lójú òpó ikanairaeni láti wá kii kú ará fẹraku Ìròyìn sọ pé wọn rí Ola Ibironke to jẹ́ ọkọ Bimbo Oshin to ṣubú lulẹ̀ ni ibi tí wón ti ń ṣe eré ìdárayá Gulf ni nnkan bí aago mẹjọ àbọ̀ ọjọ naa n'ilu Ibadan. Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ gbogbo ìgbìyànjú láti dáa padà sáyé ló ja sí pàbó, wọ́n sì gbé lọ sí ilé ìwòsàn níbi tí wọn tí kéde pé ó ti jáde láyé Nínú alaye gbọọrọ to kọ soju opo Instagram rẹ ni Bimbo Osun tí sọ pe ko burú ju kí ènìyàn pàdánù olólùfẹ́ ẹni lo, ṣùgbọ́n òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Bimbo Oshin ni òun ṣe ìdárò ọkọ òun nígbà gbogbo nítorí ó nira àti pé ó sì ń jọ bí àlá náà ni, ṣùgbọ́n òun mọ pe ibikíbi tí ọkọ òun bá wà yóò fẹ ki inú òun máa dùn ni kí ṣeé láti sọ ìrètí nù Gbajúgbajà òṣèré náà dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó dúró tíì lásìkò tí wá nílé òpó tó fi mọ́ orí adé Olubadan àti àwọn gbajúgbajà Òṣèré gbogbo. Bakan naa lo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn egbe òní Gulf Ibadan ni bí ti o ni ọkọ òun jẹ asoju ẹgbẹ́ wọn kì ó tó di ẹni àkọlẹ bo, fún gbogbo nnkan ti wọn ti nígbà tí ọkọ òun wà láàyè àti ìgbà tí ó kú tán. Bimbo Oshin dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo awon ẹgbẹ́ òṣèré pátá fún ìfẹ́ àti aduro tí. Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ Oniwo tí ìlú Ìwọ Oba Rasheed Akanbi "A oni fi iru eyi san funrawa loruko Jesu." Gbajúgbajà òṣèré náà fi kún pé pẹlu bí gbogbo àwọn ènìyàn ṣe ṣe yìí, òun mọ pe inú ọkọ ohun náà fún sí wọn níbikíbi tí ó bá wà | Dudu Heritage Kò sí ń nǹkan tí ó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ, Bimbo Oshin kọ ọrọ ìdárò lẹyin ikú ọkọ rẹ tó d'oloogbe Gbajúgbajà òṣèré tíátà Bimbo Oshin tí padà sí ojú òpó ikansiraẹni instagram lẹ́yìn oṣù diẹ tó o ti n sọfọ ikú ọkọ rẹ Dudu Heritage Ọkọ rẹ to kú ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹsàn-án ọdún 2021 tí ọ̀pọ̀ àwọn alabasisẹpọ rẹ sì jáde lójú òpó ikanairaeni láti wá kii kú ará fẹraku Ìròyìn sọ pé wọn rí Ola Ibironke to jẹ́ ọkọ Bimbo Oshin to ṣubú lulẹ̀ ni ibi tí wón ti ń ṣe eré ìdárayá Gulf ni nnkan bí aago mẹjọ àbọ̀ ọjọ naa n'ilu Ibadan. Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ gbogbo ìgbìyànjú láti dáa padà sáyé ló ja sí pàbó, wọ́n sì gbé lọ sí ilé ìwòsàn níbi tí wọn tí kéde pé ó ti jáde láyé Nínú alaye gbọọrọ to kọ soju opo Instagram rẹ ni Bimbo Osun tí sọ pe ko burú ju kí ènìyàn pàdánù olólùfẹ́ ẹni lo, ṣùgbọ́n òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Bimbo Oshin ni òun ṣe ìdárò ọkọ òun nígbà gbogbo nítorí ó nira àti pé ó sì ń jọ bí àlá náà ni, ṣùgbọ́n òun mọ pe ibikíbi tí ọkọ òun bá wà yóò fẹ ki inú òun máa dùn ni kí ṣeé láti sọ ìrètí nù Gbajúgbajà òṣèré náà dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó dúró tíì lásìkò tí wá nílé òpó tó fi mọ́ orí adé Olubadan àti àwọn gbajúgbajà Òṣèré gbogbo. Bakan naa lo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn egbe òní Gulf Ibadan ni bí ti o ni ọkọ òun jẹ asoju ẹgbẹ́ wọn kì ó tó di ẹni àkọlẹ bo, fún gbogbo nnkan ti wọn ti nígbà tí ọkọ òun wà láàyè àti ìgbà tí ó kú tán. Bimbo Oshin dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo awon ẹgbẹ́ òṣèré pátá fún ìfẹ́ àti aduro tí. Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ Oniwo tí ìlú Ìwọ Oba Rasheed Akanbi "A oni fi iru eyi san funrawa loruko Jesu." Gbajúgbajà òṣèré náà fi kún pé pẹlu bí gbogbo àwọn ènìyàn ṣe ṣe yìí, òun mọ pe inú ọkọ ohun náà fún sí wọn níbikíbi tí ó bá wà | https://www.bbc.com/yoruba/59475636 |
3politics
| Ìdẹ̀rùn yóò báwọn ọmọ Nàìjíríà, tí Tinubu bá di Ààrẹ - Aisha Buhari | Aya aarẹ orilẹede yii, Aisha Buhari ti fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe oun le fọwọ sọya lori iyansipo oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu. Aisha Buhari ni iyansipo Tinubu yoo san pupọ awọn ọmọ orilẹede Naijria si rere. O ni ọwọ eeyan dada ni Najiria wa, ti Tinuba ba di aarẹ lọdun 2023. Aya aarẹ, ti Asabe Bashir, olori awọn obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu APC soju fun, sọ eleyi nigba to n kopa ninu ifọrọwerọ kan niluu Abuja. O ni itan bi Tinubu ṣe ṣe ijọba rẹ tẹlẹ nilu Eko ti fihan pe oun gan ni ipo naa tọsi ju nitori o ni oye ati ori pipe to n fi ṣe ijọba rẹ. Aisha wa kesi oludije ọhun pe ko maṣe gbagbe awọn obinrin kete to ba ti di aarẹ orilẹede Niajiria. “Mo ti ri iwe afojusun ti Tinubu fi lede lori bii yoo ṣe ṣe ijọba rẹ, eyi to si fi mi lọkan balẹ pe iṣejọba rẹ to ba di aarẹ lọdun 2023 yoo mu ọpọlọpọ ilọsiwaju de ba orilẹde Naijiria. “Mo wa n rọ Oludije wa ko ri pe wọn mu awọn obinrin mọ awọn ọmọ igbimọ ti yoo maa ṣe agbatẹru alafia lorilẹede Naijiria “Idi ni pe gbogbo agbaye lo mọ pe ọga ni obinrin jẹ ninu ki a pese alaafia, ilọsiwaju ati idagbasoke ni awujọ wa.” Bẹẹ ba gbagbe, ẹgbẹ oselu APC kede Asiwaju Bola Ahmed Tinubu gẹgẹ bii ẹni to gbegba oroke ninu ibo abẹnu fawọn oludije sipo aarẹ ti yoo soju ẹgbẹ oselu naa lọdun 2023. Tinubu lo ni ibo to pọju ninu eto idibo naa, to si fi idi awọn oludije yoku janlẹ ninu ibo abẹnu ọhun. | Ìdẹ̀rùn yóò báwọn ọmọ Nàìjíríà, tí Tinubu bá di Ààrẹ - Aisha Buhari Aya aarẹ orilẹede yii, Aisha Buhari ti fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe oun le fọwọ sọya lori iyansipo oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu. Aisha Buhari ni iyansipo Tinubu yoo san pupọ awọn ọmọ orilẹede Naijria si rere. O ni ọwọ eeyan dada ni Najiria wa, ti Tinuba ba di aarẹ lọdun 2023. Aya aarẹ, ti Asabe Bashir, olori awọn obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu APC soju fun, sọ eleyi nigba to n kopa ninu ifọrọwerọ kan niluu Abuja. O ni itan bi Tinubu ṣe ṣe ijọba rẹ tẹlẹ nilu Eko ti fihan pe oun gan ni ipo naa tọsi ju nitori o ni oye ati ori pipe to n fi ṣe ijọba rẹ. Aisha wa kesi oludije ọhun pe ko maṣe gbagbe awọn obinrin kete to ba ti di aarẹ orilẹede Niajiria. “Mo ti ri iwe afojusun ti Tinubu fi lede lori bii yoo ṣe ṣe ijọba rẹ, eyi to si fi mi lọkan balẹ pe iṣejọba rẹ to ba di aarẹ lọdun 2023 yoo mu ọpọlọpọ ilọsiwaju de ba orilẹde Naijiria. “Mo wa n rọ Oludije wa ko ri pe wọn mu awọn obinrin mọ awọn ọmọ igbimọ ti yoo maa ṣe agbatẹru alafia lorilẹede Naijiria “Idi ni pe gbogbo agbaye lo mọ pe ọga ni obinrin jẹ ninu ki a pese alaafia, ilọsiwaju ati idagbasoke ni awujọ wa.” Bẹẹ ba gbagbe, ẹgbẹ oselu APC kede Asiwaju Bola Ahmed Tinubu gẹgẹ bii ẹni to gbegba oroke ninu ibo abẹnu fawọn oludije sipo aarẹ ti yoo soju ẹgbẹ oselu naa lọdun 2023. Tinubu lo ni ibo to pọju ninu eto idibo naa, to si fi idi awọn oludije yoku janlẹ ninu ibo abẹnu ọhun. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/c10m0216e7qo |
4religion
| TB Joshua's Arigidi-Akoko town: Òkúta tó jábọ́ tí kò pa T.B Joshua ní ìkókó, àwa táa mọ ìt | Ni ilu ibi Wolii Temitope Joshua to di oloogbe ti wọn si n ṣe eto isinku rẹ lọwọ, awọn ara ile rẹ kan ṣi n sọ pe ko dun mọ awọn bi wọn ko ṣe wa sin oku rẹ sile. Awọn iyawo ile tilẹ ni awọn gbera lọ si Eko lati lọ bere pe bawo ni eto yoo ṣe jẹ ṣugbọn wọn ko jẹ ki awọn ri iyawo Wolii Joshua. Àdánù láéláé ni fún wa tí wọn kò bá sin òkú T.B Joshua sí ìlú abinibí rẹ̀ - Ọba Arigidi-Akoko Àwòrán bí ó ṣe ńlọ rèé níbi ìsìnkú TB Joshua lónìí Wo àwọn gbajúmọ̀, òṣèré tó lọ sí ibi ètò ìsìnkú Temitope Joshua Ìtàn ayé TB Joshua tó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́ta nínú ìyà rẹ̀ Arigidi-Akoko kan gógó torí ikú TB Joshua 'Ẹ má jẹ́ kí òkú ọmọ mi ráre o ìjọba! Ẹ gbée fún mi kí n lọ sin ín - Ìyá ọmọ ti wọ́n pa ní ìwọ́de Yoruba Nation Amọṣa wọn o ri inu bi, wọn ṣi gbagbọ wipe bi wọn ṣi sin in si ilu eko, bo ba to ọgọrun ọdun, wọn yoo si gbe e wa sile ni ilu ibi rẹ tii ṣe Arigidi-Akoko. 'Ẹ má sọ pé lọ́balọ́ba kó sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù Sunday Igboho, Inú wa kò dún sí ìjọba' Mò ń rán “suit” tó ta lẹ́nu wọ́n sì gba tèmi àti ìyàwó mi gidi nínú iṣẹ télọ - Odi ọkọ àtìyàwó A ti ń rán ọ̀pọ̀ ọ̀daràn lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run láti lọ jẹ́jọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn - Ólórí iléèṣẹ́ ológun tuntun | TB Joshua's Arigidi-Akoko town: Òkúta tó jábọ́ tí kò pa T.B Joshua ní ìkókó, àwa táa mọ ìt Ni ilu ibi Wolii Temitope Joshua to di oloogbe ti wọn si n ṣe eto isinku rẹ lọwọ, awọn ara ile rẹ kan ṣi n sọ pe ko dun mọ awọn bi wọn ko ṣe wa sin oku rẹ sile. Awọn iyawo ile tilẹ ni awọn gbera lọ si Eko lati lọ bere pe bawo ni eto yoo ṣe jẹ ṣugbọn wọn ko jẹ ki awọn ri iyawo Wolii Joshua. Àdánù láéláé ni fún wa tí wọn kò bá sin òkú T.B Joshua sí ìlú abinibí rẹ̀ - Ọba Arigidi-Akoko Àwòrán bí ó ṣe ńlọ rèé níbi ìsìnkú TB Joshua lónìí Wo àwọn gbajúmọ̀, òṣèré tó lọ sí ibi ètò ìsìnkú Temitope Joshua Ìtàn ayé TB Joshua tó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́ta nínú ìyà rẹ̀ Arigidi-Akoko kan gógó torí ikú TB Joshua 'Ẹ má jẹ́ kí òkú ọmọ mi ráre o ìjọba! Ẹ gbée fún mi kí n lọ sin ín - Ìyá ọmọ ti wọ́n pa ní ìwọ́de Yoruba Nation Amọṣa wọn o ri inu bi, wọn ṣi gbagbọ wipe bi wọn ṣi sin in si ilu eko, bo ba to ọgọrun ọdun, wọn yoo si gbe e wa sile ni ilu ibi rẹ tii ṣe Arigidi-Akoko. 'Ẹ má sọ pé lọ́balọ́ba kó sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù Sunday Igboho, Inú wa kò dún sí ìjọba' Mò ń rán “suit” tó ta lẹ́nu wọ́n sì gba tèmi àti ìyàwó mi gidi nínú iṣẹ télọ - Odi ọkọ àtìyàwó A ti ń rán ọ̀pọ̀ ọ̀daràn lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run láti lọ jẹ́jọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn - Ólórí iléèṣẹ́ ológun tuntun | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57768805 |
4religion
| Yoruba gods: Wo àwọn òrìṣà méje ìṣẹ̀mbáyé tó di ilẹ̀ gbogbo àgbáyé mú | Awọn oriṣa ni ilẹ Yoruba jẹ igbagbọ awọn ẹlẹsin ibilẹ paapaa ni orilẹede Naijiria, Benin ati Togo. Ọpọlọpọ awọn onigbagbọ ninu oriṣa iṣẹmbaye ni wọn ri awọn orisa yii gẹgẹ bi ọlọrun wọn. Wọn gbagbọ wi pe awọn orisa yii ṣiṣ̣ẹ pọ fun ara wọn ni, amọ wọn ki n ṣe nkankan naa lati ọdọ Olodumare to ran wọn wa si ile aye. Ohun tí ìyàwó Adeboye ṣe ní ìgbà akọkọ tó fojú hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn Dare Pasítọ̀ Dare, ọmọ́ Pásítọ̀ Adeboye ti dágbére fáyé Ìyá àláwo tó di àjíhìnrere òjijì fi àwọn òrìṣà rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà Paapaa wọn ni igbagbọ wi pe awọn orisa yii dabi angẹli tabi iranṣẹ olodumare ti awọn eniyan ma n pe ni igba iṣoro. Lara awọn orisa naa ni Esu, Ogun, Ọbatala, Yemọja, Osun, Sango ati Ọya, ti wọn pe ni Ọrumila. In ilẹ Yoruba, awọn ̣elẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe esu jẹ oriṣa to lagbara pupọ, to si jẹ iranṣẹ laarin aye ati ọrun, to fi mọ agbede meji. Oun si ni ọkan lara awọn orisa ti o ma n tọ awọn oku sọna lẹyin ti wọn papoda. Wọn gbagbọ wipe esu ni a n ke pe ti ohun ba daru, ti eniyan si n wa ọna abayọ tabi ojutu si nkan to wọ. Bakan naa ni wọn ri ẹmi esu gẹgẹ bi orisa alarekereke, to ṣeeṣe ko tan eniyan jẹ. Awọn aṣọ pupa ati dudu ni o jọ mọ orisa yii, ti wọn si n lo ata wẹwẹ, taba mimu ati ounjẹ gbigbona lati fi bọ oriṣa yii. Ogun jẹ orisa akunlẹbọ ti wọn gbagbọ wi pe oun ni ẹni keji to lagbara julọ ninu awọn orisa meje to ku. Ogun ti gbogbo eniyan mọ pẹlu irin, ni o ma n ṣiṣẹ iwosan to si jọba lori gbogbo ohun ti a fi irin da. Awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wipe abiyamọ tootọ ni Ogun, ti o ma n ṣe atilẹyin fun ọmọde ati idile. Oun si ni wọn n pe lati bura tabi rin irinajo. Wọn gbagbọ wi pe oriṣa kan ti kii sinmi ni Ogun jẹ, to si ma n fi ẹjẹ wẹ bi omi. Amọ, ẹnikẹnị ti ẹjẹ ba n yọ ni ara rẹ ko gbọdọ sunmo idi oriṣa Ogun. Lati bọ Ogun, wọn ma n lo ewe ni ẹba titi, irin, ẹjẹ, awọn ohun ija, ẹran, ogogoro ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ọbatala jẹ ọkan lara awọn orisa meje ti o tutu pẹlu ẹbun itusilẹ ati alaafia. Amọ, oun ni awọn oloriṣa gbagbọ wi pe o ma n da awọn eniyan ti ko pe, paapaa awọn akanda eniyan. Ọbatala ni o ni suuru julọ laarin awọn ẹmi meje yii, to si ma n ṣe idajọ ododo. Oriṣa yii fẹran awọn eniyan ti kii ṣe alara gbigbona, ti wọn si le e ko ara wọn ni ijanu. Aṣọ funfun ni a mọ pẹlu Ọbatala, ti o si ma n ṣiṣẹ iwosan fun awọn to ba ni ailera, paapaa awọn akanda ẹda. Bẹẹ si ni Ọbatala kii gba oṭi kikan rara, yatọ si omi, miliki, ṣuga, ọgẹdẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ. Yemọja jẹ obinrin lara awọn orisa meje to di ile aye mu, to n gbe ninu omi, to si n jọba lori gbogbo omi nla nla. Yemọja to jẹ ẹja nla ninu odo ni ibatan Osun to jọba lori awọn omi kekeke. Awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe olupese ni Yemọja, to n pese ọmọ to si n fun awọn eniyan ni ohun meremere ninu omi, amọ o si le e fa ibinu yọ bi ẹkun omi tabi iji lile. Lailai, Ọya ati Yemọja kii ṣe ọrẹ nitori naa wọn kii gbe wọn si ibi kan naa. Awọn arinrinajo lori omi ma n bọ lẹba odo, ki wọn to bẹrẹ irinajo wọn, ki o le lo ni irọwọ-rọsẹ. Oriṣa akunlẹbọ yii ni awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe o jọba lori awọn omi kekeke, to si jẹ ibatan Yemọja. Ọsun ni wọn ma n bọ ti wọn ba n wa nkan ayọ, paapaa ọmọ tuntun jojolo. Ọsun kii tete binu, amọ ibinu rẹ ko sunwọn rara. Awọn eroja ti wọn fi n sin Osun ni omi, miliki, oyin ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ṣango jẹ ọkan lara awọn oriṣa to gbona jainjain, ti si n rọjo ina ti irin ba koju irin. Ṣango ni awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe o jẹ Ọya ati Ọsun. Ṣango ati Ogun kii ri ara wọn soju nitori wọn kii ṣe ọrẹ nitori ọta ara wọn ni wọn n ṣe. Ṣango ni o ma n ṣe idajọ nipa lilo mọnamọna, ti kii si jẹ ki ibi ṣẹlẹ si awọn ọlọlufẹ rẹ, to si fẹran obinrin, orin ati igbadun. Ọya lo kẹyin ninu awọn oriṣa meje to lagbara julọ lagbaye, ti wọn si ma fi n rọpọ orunmila nigba miran. Awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe obinrin to rẹwa ni ti o si wa ninu omi pẹlu agbara lati ṣiṣẹ iwosan ati ọmọ bibi. Eewọ ni lati pe oriṣa Ọya, Yemọja ati Ọsun papọ lẹẹkan naa, nitori ọta ni wọn, wọn kii ri Ọya soju, afi ti ẹ ba n pe awọn oriṣa mejeeje papọ ni igba kan naa. | Yoruba gods: Wo àwọn òrìṣà méje ìṣẹ̀mbáyé tó di ilẹ̀ gbogbo àgbáyé mú Awọn oriṣa ni ilẹ Yoruba jẹ igbagbọ awọn ẹlẹsin ibilẹ paapaa ni orilẹede Naijiria, Benin ati Togo. Ọpọlọpọ awọn onigbagbọ ninu oriṣa iṣẹmbaye ni wọn ri awọn orisa yii gẹgẹ bi ọlọrun wọn. Wọn gbagbọ wi pe awọn orisa yii ṣiṣ̣ẹ pọ fun ara wọn ni, amọ wọn ki n ṣe nkankan naa lati ọdọ Olodumare to ran wọn wa si ile aye. Ohun tí ìyàwó Adeboye ṣe ní ìgbà akọkọ tó fojú hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn Dare Pasítọ̀ Dare, ọmọ́ Pásítọ̀ Adeboye ti dágbére fáyé Ìyá àláwo tó di àjíhìnrere òjijì fi àwọn òrìṣà rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà Paapaa wọn ni igbagbọ wi pe awọn orisa yii dabi angẹli tabi iranṣẹ olodumare ti awọn eniyan ma n pe ni igba iṣoro. Lara awọn orisa naa ni Esu, Ogun, Ọbatala, Yemọja, Osun, Sango ati Ọya, ti wọn pe ni Ọrumila. In ilẹ Yoruba, awọn ̣elẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe esu jẹ oriṣa to lagbara pupọ, to si jẹ iranṣẹ laarin aye ati ọrun, to fi mọ agbede meji. Oun si ni ọkan lara awọn orisa ti o ma n tọ awọn oku sọna lẹyin ti wọn papoda. Wọn gbagbọ wipe esu ni a n ke pe ti ohun ba daru, ti eniyan si n wa ọna abayọ tabi ojutu si nkan to wọ. Bakan naa ni wọn ri ẹmi esu gẹgẹ bi orisa alarekereke, to ṣeeṣe ko tan eniyan jẹ. Awọn aṣọ pupa ati dudu ni o jọ mọ orisa yii, ti wọn si n lo ata wẹwẹ, taba mimu ati ounjẹ gbigbona lati fi bọ oriṣa yii. Ogun jẹ orisa akunlẹbọ ti wọn gbagbọ wi pe oun ni ẹni keji to lagbara julọ ninu awọn orisa meje to ku. Ogun ti gbogbo eniyan mọ pẹlu irin, ni o ma n ṣiṣẹ iwosan to si jọba lori gbogbo ohun ti a fi irin da. Awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wipe abiyamọ tootọ ni Ogun, ti o ma n ṣe atilẹyin fun ọmọde ati idile. Oun si ni wọn n pe lati bura tabi rin irinajo. Wọn gbagbọ wi pe oriṣa kan ti kii sinmi ni Ogun jẹ, to si ma n fi ẹjẹ wẹ bi omi. Amọ, ẹnikẹnị ti ẹjẹ ba n yọ ni ara rẹ ko gbọdọ sunmo idi oriṣa Ogun. Lati bọ Ogun, wọn ma n lo ewe ni ẹba titi, irin, ẹjẹ, awọn ohun ija, ẹran, ogogoro ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ọbatala jẹ ọkan lara awọn orisa meje ti o tutu pẹlu ẹbun itusilẹ ati alaafia. Amọ, oun ni awọn oloriṣa gbagbọ wi pe o ma n da awọn eniyan ti ko pe, paapaa awọn akanda eniyan. Ọbatala ni o ni suuru julọ laarin awọn ẹmi meje yii, to si ma n ṣe idajọ ododo. Oriṣa yii fẹran awọn eniyan ti kii ṣe alara gbigbona, ti wọn si le e ko ara wọn ni ijanu. Aṣọ funfun ni a mọ pẹlu Ọbatala, ti o si ma n ṣiṣẹ iwosan fun awọn to ba ni ailera, paapaa awọn akanda ẹda. Bẹẹ si ni Ọbatala kii gba oṭi kikan rara, yatọ si omi, miliki, ṣuga, ọgẹdẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ. Yemọja jẹ obinrin lara awọn orisa meje to di ile aye mu, to n gbe ninu omi, to si n jọba lori gbogbo omi nla nla. Yemọja to jẹ ẹja nla ninu odo ni ibatan Osun to jọba lori awọn omi kekeke. Awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe olupese ni Yemọja, to n pese ọmọ to si n fun awọn eniyan ni ohun meremere ninu omi, amọ o si le e fa ibinu yọ bi ẹkun omi tabi iji lile. Lailai, Ọya ati Yemọja kii ṣe ọrẹ nitori naa wọn kii gbe wọn si ibi kan naa. Awọn arinrinajo lori omi ma n bọ lẹba odo, ki wọn to bẹrẹ irinajo wọn, ki o le lo ni irọwọ-rọsẹ. Oriṣa akunlẹbọ yii ni awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe o jọba lori awọn omi kekeke, to si jẹ ibatan Yemọja. Ọsun ni wọn ma n bọ ti wọn ba n wa nkan ayọ, paapaa ọmọ tuntun jojolo. Ọsun kii tete binu, amọ ibinu rẹ ko sunwọn rara. Awọn eroja ti wọn fi n sin Osun ni omi, miliki, oyin ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ṣango jẹ ọkan lara awọn oriṣa to gbona jainjain, ti si n rọjo ina ti irin ba koju irin. Ṣango ni awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe o jẹ Ọya ati Ọsun. Ṣango ati Ogun kii ri ara wọn soju nitori wọn kii ṣe ọrẹ nitori ọta ara wọn ni wọn n ṣe. Ṣango ni o ma n ṣe idajọ nipa lilo mọnamọna, ti kii si jẹ ki ibi ṣẹlẹ si awọn ọlọlufẹ rẹ, to si fẹran obinrin, orin ati igbadun. Ọya lo kẹyin ninu awọn oriṣa meje to lagbara julọ lagbaye, ti wọn si ma fi n rọpọ orunmila nigba miran. Awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe obinrin to rẹwa ni ti o si wa ninu omi pẹlu agbara lati ṣiṣẹ iwosan ati ọmọ bibi. Eewọ ni lati pe oriṣa Ọya, Yemọja ati Ọsun papọ lẹẹkan naa, nitori ọta ni wọn, wọn kii ri Ọya soju, afi ti ẹ ba n pe awọn oriṣa mejeeje papọ ni igba kan naa. | https://www.bbc.com/yoruba/56995564 |
5sports
| Ìgbà méjìlá tí Super Falcons kojú South Africa ní WAFCON, tí wọn sì dáṣọ ìyà sí wọn lọ́rùn | Ninu idije bọọlu afẹsẹgba to jẹ ti awọn obinrin ilẹ̀ Afrika tó n waye lọwọ ni orile-ede Morocco, ọjọ Aje, ọjọ́ kẹrin, oṣu Keje, ni ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons yoo gba ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ pẹlu orile-ede South Africa. Papa ìṣeré Prince Heritier Moulay El Hassan, n'ilu Rabat, ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yoo ti waye laago mẹfa irọlẹ. Igba àkọ́kọ́ kọ re e ti awọn mejeeeji n koju ara wọn. Ni gbogbo igba ti wọn ba pade lori papa, lo ma n gbona janjan bi ẹ̀kọ. Eyi ko sẹ́yìn bo ṣe jẹ́ pe ẹgbẹ́ agbabòọlu mejeeji, Super Falcons ati Bayana Bayana, lo jẹ ogbontarigi ninu bọọlu gbigba. Àmọ́ o, agba lẹtù, ọmọde lawó. Ninu igba mọkanla tí idije WAFCON ti waye, igba mẹsan-an ni Naijiria gba ife ẹyẹ. Ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo iye igba ti South Africa ati Naijiria ti koju ara wọn: Ọdún naa ni igba akọkọ ti ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji koju ara wọn ninu idije bọọlu awọn obinrin ni Africa. Ewuro ayo mẹrin si odo ni Naijiria gbo si South Africa lẹ́nu, ni papa ìṣeré n'ilu Ibadan. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni abala akọkọ ni ipele aṣekagba idije WAFCON lọdun 1995. Ọdún naa paapaa ni igba àkọ́kọ́ ti Bayana Bayana kopa ninu idije naa. Boya nitori naa ni Naijiria fi lu wọn lalu bolẹ. Naijiria ko fi mọ nibẹ, nigba ti wọn tun jọ pade n'ilu Johannesburg lorile-ede South Africa, ami ayo meje si ẹyọkan ni Naijiria fi fọ́ South Africa mọ ilé baba wọn. A fi bi ẹni pe wọn fi ẹgba iya le Super Falcons Naijiria lọwọ lati ma a fi lu South Africa ni. Ninu idije wafcon to tun waye lọdun 2000, wọn tun jọ pade. South Africa gbiyanju, wọn faraya bii ki wọn o gba ẹsan ìyà meji àkọ́kọ́, àmọ́ Naijiria tun rún wọn mọ́lẹ̀ nilẹ baba wọn, nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to waye n'ilu Boksburg. Àwọn agbabọọlu Naijiria méjì,Olaitan Yusuf and Stella Mbachu lo rọ̀jò iya le Bayana Bayana lori. Naijiria ati South Africa pade fun igba kẹrin lọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2002, ni idije wafcon. Ipele semi-final ni wọn ti pade, lẹyin ti Bayana Bayana borí ni ìpín B, nibi ti wọn wa pẹlu Cameroon, Angola, ati Zimbabwe. Papa ìṣeré to wa n'ilu Warri, nipinlẹ Delta, ní Super Falcons ti lọ wọn mọlẹ bi ata irẹsi eléwé. Fun igba akọkọ, ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji pade ni ibẹrẹ pẹpẹ idije WAFCON lọdun naa. Naijiria lo bori. Wọn tun jọ pade fun igba kejì ninu idije naa ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to kẹhin ni ìpín tí wọn pin wọn si, group stage. Ami ayo meji si odo ni Naijiria tun fi bori wọn. Ọdún yii ni igba àkọ́kọ́ ti Naijiria ko gba ife ẹyẹ WAFCON. Orile-ede Equatorial Guinea nì idije naa ti waye lọdun 2008. Ipo kẹta ni Naijiria ṣe. Àmọ́ ibẹrẹ pẹpẹ idije naa ni àwọn ati South Africa ti pade ni papa ìṣeré Estadio La Libertad, Bata. Ami ayo kan si odo ni wọn gbá. Àgbò to tàdí mẹ́yìn, agbara lo lọ mu wa ni ọrọ Naijiria ni WAFCON 2010. South Africa wa lara awọn ti wọn fi iya jẹ, ti wọn tun fi rí ife ẹyẹ idije naa gba lẹẹkan si i. Wọn dáná ami ayo meji si ẹyọkan si wọn lara nilẹ baba wọn ni papa ìṣeré Sinaba Stadium. Fun igba àkọ́kọ́, ninu itan wafcon, South Africa fi ẹyin Naijiria janlẹ pẹlu ami kan si odo. Lílù ti Bayana Bayana naa wọn, ja wọn danu ṣáájú ki idije to wọ semi-final. Equatorial Guinea lo tun gba ife ẹyẹ fun igba keji lọdun naa. Ṣe ẹ o gbagbe pe South Africa lo ja Naijiria kuro ninu idije naa, pẹlu ami ayo kan si odo. Wọn o de ipele semi-final. Ikanra ni Asisat Oshoala fi gbẹsan lara South Africa nigba ti wọn pade ni Windhoek, nigba ti wọn jọ pade. Ipele aṣekagba idije naa ni wọn tun ti pade, lẹyin naa. Ami ayo méjì si odo ni Naijiria fun wọn ni papa ìṣeré Sam Nujoma, ti wọn tun fi gba ife ẹyẹ. Wọn tun jọ pade ni ipele semi-final ni wafcon to waye ni Cameroon lọdun 2016. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa gbona pupọ, ṣùgbọ́n Naijiria pada bori pẹlu ami kan si odo nigba ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọ isẹju mẹrinlelaadọta. Lọtẹ yii, àwọn agbabọọlu obìnrin South Africa ko ṣeré rara. Àwọn pẹlu Naijiria lo jọ koju ara wọn ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́, nibi idije WAFCON to waye ni Ghana, Ghana 2018. Ami ayo kan si odo ni South Africa fun Naijiria. Igbẹyin ni alayo n ta ni Super Falcons fi ọ̀rọ̀ ṣe nigba ti wọn jọ tun pade ni idije aṣekagba. Ọmi òdo ni wọn jọ kọ́kọ́ ta. Ṣugbọn Naijiria bori pẹlu ami mẹrin si mẹta nigba ti wọn gba pẹnariti. Ọdún naa ni igba kẹsàn-án ti Naijiria gba ife ẹyẹ WAFCON. Taa ni yoo bori ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ ni Morocco? | Ìgbà méjìlá tí Super Falcons kojú South Africa ní WAFCON, tí wọn sì dáṣọ ìyà sí wọn lọ́rùn Ninu idije bọọlu afẹsẹgba to jẹ ti awọn obinrin ilẹ̀ Afrika tó n waye lọwọ ni orile-ede Morocco, ọjọ Aje, ọjọ́ kẹrin, oṣu Keje, ni ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons yoo gba ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ pẹlu orile-ede South Africa. Papa ìṣeré Prince Heritier Moulay El Hassan, n'ilu Rabat, ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yoo ti waye laago mẹfa irọlẹ. Igba àkọ́kọ́ kọ re e ti awọn mejeeeji n koju ara wọn. Ni gbogbo igba ti wọn ba pade lori papa, lo ma n gbona janjan bi ẹ̀kọ. Eyi ko sẹ́yìn bo ṣe jẹ́ pe ẹgbẹ́ agbabòọlu mejeeji, Super Falcons ati Bayana Bayana, lo jẹ ogbontarigi ninu bọọlu gbigba. Àmọ́ o, agba lẹtù, ọmọde lawó. Ninu igba mọkanla tí idije WAFCON ti waye, igba mẹsan-an ni Naijiria gba ife ẹyẹ. Ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo iye igba ti South Africa ati Naijiria ti koju ara wọn: Ọdún naa ni igba akọkọ ti ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji koju ara wọn ninu idije bọọlu awọn obinrin ni Africa. Ewuro ayo mẹrin si odo ni Naijiria gbo si South Africa lẹ́nu, ni papa ìṣeré n'ilu Ibadan. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni abala akọkọ ni ipele aṣekagba idije WAFCON lọdun 1995. Ọdún naa paapaa ni igba àkọ́kọ́ ti Bayana Bayana kopa ninu idije naa. Boya nitori naa ni Naijiria fi lu wọn lalu bolẹ. Naijiria ko fi mọ nibẹ, nigba ti wọn tun jọ pade n'ilu Johannesburg lorile-ede South Africa, ami ayo meje si ẹyọkan ni Naijiria fi fọ́ South Africa mọ ilé baba wọn. A fi bi ẹni pe wọn fi ẹgba iya le Super Falcons Naijiria lọwọ lati ma a fi lu South Africa ni. Ninu idije wafcon to tun waye lọdun 2000, wọn tun jọ pade. South Africa gbiyanju, wọn faraya bii ki wọn o gba ẹsan ìyà meji àkọ́kọ́, àmọ́ Naijiria tun rún wọn mọ́lẹ̀ nilẹ baba wọn, nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to waye n'ilu Boksburg. Àwọn agbabọọlu Naijiria méjì,Olaitan Yusuf and Stella Mbachu lo rọ̀jò iya le Bayana Bayana lori. Naijiria ati South Africa pade fun igba kẹrin lọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2002, ni idije wafcon. Ipele semi-final ni wọn ti pade, lẹyin ti Bayana Bayana borí ni ìpín B, nibi ti wọn wa pẹlu Cameroon, Angola, ati Zimbabwe. Papa ìṣeré to wa n'ilu Warri, nipinlẹ Delta, ní Super Falcons ti lọ wọn mọlẹ bi ata irẹsi eléwé. Fun igba akọkọ, ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji pade ni ibẹrẹ pẹpẹ idije WAFCON lọdun naa. Naijiria lo bori. Wọn tun jọ pade fun igba kejì ninu idije naa ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to kẹhin ni ìpín tí wọn pin wọn si, group stage. Ami ayo meji si odo ni Naijiria tun fi bori wọn. Ọdún yii ni igba àkọ́kọ́ ti Naijiria ko gba ife ẹyẹ WAFCON. Orile-ede Equatorial Guinea nì idije naa ti waye lọdun 2008. Ipo kẹta ni Naijiria ṣe. Àmọ́ ibẹrẹ pẹpẹ idije naa ni àwọn ati South Africa ti pade ni papa ìṣeré Estadio La Libertad, Bata. Ami ayo kan si odo ni wọn gbá. Àgbò to tàdí mẹ́yìn, agbara lo lọ mu wa ni ọrọ Naijiria ni WAFCON 2010. South Africa wa lara awọn ti wọn fi iya jẹ, ti wọn tun fi rí ife ẹyẹ idije naa gba lẹẹkan si i. Wọn dáná ami ayo meji si ẹyọkan si wọn lara nilẹ baba wọn ni papa ìṣeré Sinaba Stadium. Fun igba àkọ́kọ́, ninu itan wafcon, South Africa fi ẹyin Naijiria janlẹ pẹlu ami kan si odo. Lílù ti Bayana Bayana naa wọn, ja wọn danu ṣáájú ki idije to wọ semi-final. Equatorial Guinea lo tun gba ife ẹyẹ fun igba keji lọdun naa. Ṣe ẹ o gbagbe pe South Africa lo ja Naijiria kuro ninu idije naa, pẹlu ami ayo kan si odo. Wọn o de ipele semi-final. Ikanra ni Asisat Oshoala fi gbẹsan lara South Africa nigba ti wọn pade ni Windhoek, nigba ti wọn jọ pade. Ipele aṣekagba idije naa ni wọn tun ti pade, lẹyin naa. Ami ayo méjì si odo ni Naijiria fun wọn ni papa ìṣeré Sam Nujoma, ti wọn tun fi gba ife ẹyẹ. Wọn tun jọ pade ni ipele semi-final ni wafcon to waye ni Cameroon lọdun 2016. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa gbona pupọ, ṣùgbọ́n Naijiria pada bori pẹlu ami kan si odo nigba ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọ isẹju mẹrinlelaadọta. Lọtẹ yii, àwọn agbabọọlu obìnrin South Africa ko ṣeré rara. Àwọn pẹlu Naijiria lo jọ koju ara wọn ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́, nibi idije WAFCON to waye ni Ghana, Ghana 2018. Ami ayo kan si odo ni South Africa fun Naijiria. Igbẹyin ni alayo n ta ni Super Falcons fi ọ̀rọ̀ ṣe nigba ti wọn jọ tun pade ni idije aṣekagba. Ọmi òdo ni wọn jọ kọ́kọ́ ta. Ṣugbọn Naijiria bori pẹlu ami mẹrin si mẹta nigba ti wọn gba pẹnariti. Ọdún naa ni igba kẹsàn-án ti Naijiria gba ife ẹyẹ WAFCON. Taa ni yoo bori ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ ni Morocco? | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cld2gl97eypo |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.