labels
class label
5 classes
headline
stringlengths
38
163
text
stringlengths
74
42.6k
headline_text
stringlengths
142
42.7k
url
stringlengths
35
53
1entertainment
Duncan Mighty: Ọlọ́pàá fi pampẹ́ mú olórín tàkasúfèé lórí ẹ̀sùn jíbítí mílíọ̀nù mọ́kànlá
Ajọ ọlọpaa ipinlẹ Imo ti fi pampẹ ofin mu gbajugbaja olorin takasufe Duncan Mighty, nipinlẹ ọhun lori ẹsun jibiti. Alokoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Ikeokwu Godson Orland fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC. O ni, kii ṣe pe wọn ji olorin ọhun gbe gẹgẹ bi iroyin ẹlẹjẹ ti awọn kan n gbe kiri lori itakun agbaye, ṣugbọn ahamọ ọlọpaa lo wa. Ikeokwu ṣalaye pe wọn ko ṣẹkẹṣẹkẹ si Duncan Mighty lọwọ lẹyin to gba miliọnu mọkanla lọwọ ipinlẹ Imo fun iṣẹ orin ati awọn nnkan mii, ti ko si ṣe iṣe ọhun. O ṣalaye pe olorin kan to ṣẹṣẹ n bọ, M2 lọ kọwe ẹsun ti wọn fi gbe e. Ikeokwu tẹsiwaju pe wọn ti gbe Duncan Mighty ṣaaju akoko yii, to si jẹwọ pe lootọ ni oun gba owo naa. Ọlọpaa sọ pe olorin ọhun ni oun ko lee da owo iṣẹ naa pada ayafi ti ijọba ipinlẹ Imo ba fagile adehun iṣẹ ọhun. Agbẹmusọ ajọ ọlọpaa pari ọrọ rẹ pe, ijọba ti wọgile adehun iṣe naa ṣugbọn Duncan Mighty kọ lati da owo pada. Eredi ree ti wọn ṣe fi ofin mu.
Duncan Mighty: Ọlọ́pàá fi pampẹ́ mú olórín tàkasúfèé lórí ẹ̀sùn jíbítí mílíọ̀nù mọ́kànlá Ajọ ọlọpaa ipinlẹ Imo ti fi pampẹ ofin mu gbajugbaja olorin takasufe Duncan Mighty, nipinlẹ ọhun lori ẹsun jibiti. Alokoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Ikeokwu Godson Orland fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC. O ni, kii ṣe pe wọn ji olorin ọhun gbe gẹgẹ bi iroyin ẹlẹjẹ ti awọn kan n gbe kiri lori itakun agbaye, ṣugbọn ahamọ ọlọpaa lo wa. Ikeokwu ṣalaye pe wọn ko ṣẹkẹṣẹkẹ si Duncan Mighty lọwọ lẹyin to gba miliọnu mọkanla lọwọ ipinlẹ Imo fun iṣẹ orin ati awọn nnkan mii, ti ko si ṣe iṣe ọhun. O ṣalaye pe olorin kan to ṣẹṣẹ n bọ, M2 lọ kọwe ẹsun ti wọn fi gbe e. Ikeokwu tẹsiwaju pe wọn ti gbe Duncan Mighty ṣaaju akoko yii, to si jẹwọ pe lootọ ni oun gba owo naa. Ọlọpaa sọ pe olorin ọhun ni oun ko lee da owo iṣẹ naa pada ayafi ti ijọba ipinlẹ Imo ba fagile adehun iṣẹ ọhun. Agbẹmusọ ajọ ọlọpaa pari ọrọ rẹ pe, ijọba ti wọgile adehun iṣe naa ṣugbọn Duncan Mighty kọ lati da owo pada. Eredi ree ti wọn ṣe fi ofin mu.
https://www.bbc.com/yoruba/50795323
5sports
Arsenal fọ́ Sevilla lẹ́nu pẹ̀lú góòlù 6-0
Goolu mẹta ṣangiliti ni atamatase tuntun ti ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ṣẹṣẹ ra, Gabriel Jesus gba wọle sawọn lasiko ti Arsenal fi na Sevilla ni goolu mẹfa si odo ni idije ife ẹyẹ Emirates Cup to waye lọjọ. Bukayọ Saka naa gba bọọlu wọle sawọn ni igba meji. Ki ifẹsẹwọnsẹ naa to wọ iṣẹju mọkandinlogun ni Arsenal goke pẹlu goolu mẹrin si odo. Eddie Nketia lo wa fọba lee lori. Emirate Cup jẹ idije igbaradi fun saa bọọlu to n bọ lọna eyi ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu kan ti ileeṣẹ Emirates n ṣe agbatẹru fun maa n gba lọdọọdun ki ipenija ajakalẹ arun COVID-19 to de ba a lọdun 2020 ati ọdun 2021. Awọn ifẹsẹwọnsẹ miran to tun waye lọjọ abamẹta Ni ilu Oslo lorilẹede Norway ni ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ laarin Manchester United ati Athletico Madrid ti waye. Amọṣa nnkan ko fi gbogbo ara ṣe ẹnuure fun Manchester United. Joao Felix lo bu omi pa ireti wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ naa nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa ti n rebi ati danu duro. Amọṣa, alamojuto ifẹsẹwọnsẹ naa, iyẹn rẹfiri fun agbabọọlu Manchester United lọwọ aaringbungbun papa, Fred ni kaadi pupa fun aṣemaṣe lẹyin ti goolu naa waye. Ni ifẹsẹwnsẹ to waye laarin Chelsea ati Udinese ni papa iṣire Dancia arena nilu Udine lorilẹede Italy. Goolu meji lati ẹsẹ Ruben Loftus -Cheek ati Hakim Ziyech lo fun Chelsea ni igara olubori.
Arsenal fọ́ Sevilla lẹ́nu pẹ̀lú góòlù 6-0 Goolu mẹta ṣangiliti ni atamatase tuntun ti ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ṣẹṣẹ ra, Gabriel Jesus gba wọle sawọn lasiko ti Arsenal fi na Sevilla ni goolu mẹfa si odo ni idije ife ẹyẹ Emirates Cup to waye lọjọ. Bukayọ Saka naa gba bọọlu wọle sawọn ni igba meji. Ki ifẹsẹwọnsẹ naa to wọ iṣẹju mọkandinlogun ni Arsenal goke pẹlu goolu mẹrin si odo. Eddie Nketia lo wa fọba lee lori. Emirate Cup jẹ idije igbaradi fun saa bọọlu to n bọ lọna eyi ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu kan ti ileeṣẹ Emirates n ṣe agbatẹru fun maa n gba lọdọọdun ki ipenija ajakalẹ arun COVID-19 to de ba a lọdun 2020 ati ọdun 2021. Awọn ifẹsẹwọnsẹ miran to tun waye lọjọ abamẹta Ni ilu Oslo lorilẹede Norway ni ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ laarin Manchester United ati Athletico Madrid ti waye. Amọṣa nnkan ko fi gbogbo ara ṣe ẹnuure fun Manchester United. Joao Felix lo bu omi pa ireti wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ naa nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa ti n rebi ati danu duro. Amọṣa, alamojuto ifẹsẹwọnsẹ naa, iyẹn rẹfiri fun agbabọọlu Manchester United lọwọ aaringbungbun papa, Fred ni kaadi pupa fun aṣemaṣe lẹyin ti goolu naa waye. Ni ifẹsẹwnsẹ to waye laarin Chelsea ati Udinese ni papa iṣire Dancia arena nilu Udine lorilẹede Italy. Goolu meji lati ẹsẹ Ruben Loftus -Cheek ati Hakim Ziyech lo fun Chelsea ni igara olubori.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/clmkgxglrl9o
4religion
TB Joshua burial: Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tó lọ sí ibi ètò ìsìnkú Temitope Joshua
Eto ayẹyẹ isin idagbere ati isinku gbajugbaja wolii, Temitope Balogun Joshua ti n waye. Nibi ayẹyẹ naa to ti bẹrẹ ni ile ijọsin Synagogue Church of All Nations, SCOAN, to wa ni agbegbe Ikotun, nipinlẹ Eko, lati ri awọn gbajumọ lawujọ. Lara awọn ti a ri nibẹ ni oṣerebinrin Jumoke George, Ronke Ojo, Femi Branch. Koda, Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, ati Minisita Naijiria nigba kan fun irianjo oju ofurufu, Femi Fani-Kayode, naa ba wọn kopa. Hàà! Yomi wàá ṣẹ̀wọ̀n o! Oò ṣe bí ọlọ́pọlọ rárá, ò kàn ń fi àṣírí Baba Ijesha àti Iyabo Ojo gòkè ni - Femi Branch Kò jọọ́, adájọ wọ́gilé gbígba onídùró Dibu Ojerinde lórí ẹ̀sùn àjẹbánu ₦5.2 bílíọ̀nù ní JAMB Ó di èèwọ̀ láti rán ọlọ́pàá, sójà, DSS wá sí ilẹ̀ Yoruba láì sọ̀ fún wa - Àpapọ̀ gómínà ní ilẹ̀ Yoruba Bimpe Oyebade tú àṣírí bí Yomi ṣe ń gbógun tìí torí ìbalòpọ̀ Sàdáńkátà! Ẹ̀yin ẹ̀létò ààbò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkọlù sí ilé Sunday Igboho - Ààrẹ Buhari Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo Ninu ọrọ ti Gani Adams ba BBC Yoruba sọ, o ni oloogbe TB Joshua kii sẹ ajihinrere nikan, o tun jẹ alaanu ọpọlọpọ eniyan. O ṣalaye pe inu ọ̀fọ̀ ni awọn ara ilu Arigidi-Akoko, nibi ti Joshua ti wa. Ọmọ ilu Arigidi naa ni Gani Adams. "Ìpè iṣẹ́ ìránṣẹ́ TB Joshua ló mú mi bí ọmọ mi wẹ́rẹ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀" Àlùfáà kan níbi tí wón bí Jesu sí tan àbẹ̀là nítorí ikú T.B. Joshua Mo rí òkú TB Joshua tó yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ - Jaiye Kuti Ìtàn ayé TB Joshua tó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́ta nínú ìyà rẹ̀
TB Joshua burial: Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tó lọ sí ibi ètò ìsìnkú Temitope Joshua Eto ayẹyẹ isin idagbere ati isinku gbajugbaja wolii, Temitope Balogun Joshua ti n waye. Nibi ayẹyẹ naa to ti bẹrẹ ni ile ijọsin Synagogue Church of All Nations, SCOAN, to wa ni agbegbe Ikotun, nipinlẹ Eko, lati ri awọn gbajumọ lawujọ. Lara awọn ti a ri nibẹ ni oṣerebinrin Jumoke George, Ronke Ojo, Femi Branch. Koda, Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, ati Minisita Naijiria nigba kan fun irianjo oju ofurufu, Femi Fani-Kayode, naa ba wọn kopa. Hàà! Yomi wàá ṣẹ̀wọ̀n o! Oò ṣe bí ọlọ́pọlọ rárá, ò kàn ń fi àṣírí Baba Ijesha àti Iyabo Ojo gòkè ni - Femi Branch Kò jọọ́, adájọ wọ́gilé gbígba onídùró Dibu Ojerinde lórí ẹ̀sùn àjẹbánu ₦5.2 bílíọ̀nù ní JAMB Ó di èèwọ̀ láti rán ọlọ́pàá, sójà, DSS wá sí ilẹ̀ Yoruba láì sọ̀ fún wa - Àpapọ̀ gómínà ní ilẹ̀ Yoruba Bimpe Oyebade tú àṣírí bí Yomi ṣe ń gbógun tìí torí ìbalòpọ̀ Sàdáńkátà! Ẹ̀yin ẹ̀létò ààbò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkọlù sí ilé Sunday Igboho - Ààrẹ Buhari Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo Ninu ọrọ ti Gani Adams ba BBC Yoruba sọ, o ni oloogbe TB Joshua kii sẹ ajihinrere nikan, o tun jẹ alaanu ọpọlọpọ eniyan. O ṣalaye pe inu ọ̀fọ̀ ni awọn ara ilu Arigidi-Akoko, nibi ti Joshua ti wa. Ọmọ ilu Arigidi naa ni Gani Adams. "Ìpè iṣẹ́ ìránṣẹ́ TB Joshua ló mú mi bí ọmọ mi wẹ́rẹ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀" Àlùfáà kan níbi tí wón bí Jesu sí tan àbẹ̀là nítorí ikú T.B. Joshua Mo rí òkú TB Joshua tó yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ - Jaiye Kuti Ìtàn ayé TB Joshua tó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́ta nínú ìyà rẹ̀
https://www.bbc.com/yoruba/awon-iroyin-miran-57739022
1entertainment
Aisha Lawal: Ẹni tó kéde pé mo kú yóò rí ìbínú Ọlọ́run
Igbe hà hà ni ó gba ẹni àwọn ènìyàn lójú ìpó ìkànsíraẹni Instagram Aisha Lawal, lẹ́yìn ti ó jáde wá láti sọ nǹkan ti àwọn kan kọ nípa rẹ. Gẹ́gẹ́ bí gbajúgbajà òṣèré tiata náà ṣe sọ lásìkò tó n bá àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ loju opo Instagram rẹ̀, ó ṣàlàyé pé, òun kò kú o. Bakan naa lo ni òun kò ṣe àìsàn, sùgbọ́n òun kò mọ idí ti ẹni tó n gbé RIP, itumọ eyi tii se ‘Sun re o’ sí orí fótò òun, ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀. Sáájú ni fótò kan tí n jà ràìnràìn lori ayelujara, eyi tó ṣàfihan ọmọ tuntun kan ati Aisha Lawal lórí ìbùsùn nilé ìwòsàn àti fótò rẹ̀. Ẹni to gbe fọto rẹ sita yii lo kọ àkọ́lé pé, "ìkà ènìyàn nìkan ní yóò rí nǹkan yìí ti kò ni tẹ RIP, arábìnrin yìí bímọ ọkunrin làntì tan, ló bá kú. Aisha Lawal ní sàdédé ni òun rí àwọn olólùfẹ́ òun ti wọ́n n fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ lórí Intagram, ti àwọn to mọ Nọ́mbà aago ilewọ òun sì ń pè oun pé àwọn gbọ́ pé ó kú. "Lẹ́yìn náà ni mo wá lọ sí orí ayélujára níbí tí mo ti rí nǹkan ti ẹni náà kọ" "Mí ò mọ nǹkan ti ẹni tó n ṣe irú nǹkan báyìí fẹ́ gbà o, ní tèmí mó fi ẹni náà lẹ fún ìdájọ́ Ọlọ́run" Bakan naa lo fi kun pe oun ki yoo ku iku kiku kan, bikose yiye lagbara Ọlọrun. Ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ Aisha Lawal náà bẹnu atẹ lu iru iwa ibi báyìí, to si ni ẹnikẹni to ba kede pe oun ku, yoo ri ibinu Ọlọrun. O fikun pe oun yoo ri ileri Ọlrun lori aye oun, tori oun n sin Ọlọrun Alaaye, gbogbo irinsẹ esu ti wọn ba si se doju kọ oun, ki yoo se rere.
Aisha Lawal: Ẹni tó kéde pé mo kú yóò rí ìbínú Ọlọ́run Igbe hà hà ni ó gba ẹni àwọn ènìyàn lójú ìpó ìkànsíraẹni Instagram Aisha Lawal, lẹ́yìn ti ó jáde wá láti sọ nǹkan ti àwọn kan kọ nípa rẹ. Gẹ́gẹ́ bí gbajúgbajà òṣèré tiata náà ṣe sọ lásìkò tó n bá àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ loju opo Instagram rẹ̀, ó ṣàlàyé pé, òun kò kú o. Bakan naa lo ni òun kò ṣe àìsàn, sùgbọ́n òun kò mọ idí ti ẹni tó n gbé RIP, itumọ eyi tii se ‘Sun re o’ sí orí fótò òun, ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀. Sáájú ni fótò kan tí n jà ràìnràìn lori ayelujara, eyi tó ṣàfihan ọmọ tuntun kan ati Aisha Lawal lórí ìbùsùn nilé ìwòsàn àti fótò rẹ̀. Ẹni to gbe fọto rẹ sita yii lo kọ àkọ́lé pé, "ìkà ènìyàn nìkan ní yóò rí nǹkan yìí ti kò ni tẹ RIP, arábìnrin yìí bímọ ọkunrin làntì tan, ló bá kú. Aisha Lawal ní sàdédé ni òun rí àwọn olólùfẹ́ òun ti wọ́n n fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ lórí Intagram, ti àwọn to mọ Nọ́mbà aago ilewọ òun sì ń pè oun pé àwọn gbọ́ pé ó kú. "Lẹ́yìn náà ni mo wá lọ sí orí ayélujára níbí tí mo ti rí nǹkan ti ẹni náà kọ" "Mí ò mọ nǹkan ti ẹni tó n ṣe irú nǹkan báyìí fẹ́ gbà o, ní tèmí mó fi ẹni náà lẹ fún ìdájọ́ Ọlọ́run" Bakan naa lo fi kun pe oun ki yoo ku iku kiku kan, bikose yiye lagbara Ọlọrun. Ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ Aisha Lawal náà bẹnu atẹ lu iru iwa ibi báyìí, to si ni ẹnikẹni to ba kede pe oun ku, yoo ri ibinu Ọlọrun. O fikun pe oun yoo ri ileri Ọlrun lori aye oun, tori oun n sin Ọlọrun Alaaye, gbogbo irinsẹ esu ti wọn ba si se doju kọ oun, ki yoo se rere.
https://www.bbc.com/yoruba/media-56926395
5sports
Brighton vs Tottenham: Aṣọ́lé Tottenham, Hugo Lloris dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn ìyà àjẹtúnjẹ lórí pápá Brighton
Kaka ki ewe agbọn dẹ, niṣe lo n le koko sii. Kaka ko san fun ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham, niṣe lo buru si o. Ẹgbẹ agbabọọlu Brighton & Hove Albion lo ṣe Tottenham bi ọṣẹ tii ṣoju ninu ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League lọjọ Abamẹta. Ami ayo mẹta ọtọọtọ ni wọn Brighton fi ṣagba Tottenham eleyi to jẹ iyanlẹnu fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu. Balogun ati aṣọle ikọ Tottenham, Hugo Lloris lo kọkọ tasẹ agẹrẹ bi Tacha lo ba mu bọọlu bọ sinu awọn ara rẹ. Laipẹ ni aṣọle fọwọ ṣeeṣe debi pe wọn ni lati gbe lọ sile iwosan lati ori papa. Ṣugbọn bi iya nla ba gbeni sanlẹ, kekere a gori ẹni ni Brighton fi ṣe fun Tottenham lẹyin ti wọn fi ọba lee pẹlu goolu meji. Lẹyin ọ rẹyin, Brighton ṣina iya fun Tottenham pẹlu ami ayo mẹta sodo lairo tẹlẹ.
Brighton vs Tottenham: Aṣọ́lé Tottenham, Hugo Lloris dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn ìyà àjẹtúnjẹ lórí pápá Brighton Kaka ki ewe agbọn dẹ, niṣe lo n le koko sii. Kaka ko san fun ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham, niṣe lo buru si o. Ẹgbẹ agbabọọlu Brighton & Hove Albion lo ṣe Tottenham bi ọṣẹ tii ṣoju ninu ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League lọjọ Abamẹta. Ami ayo mẹta ọtọọtọ ni wọn Brighton fi ṣagba Tottenham eleyi to jẹ iyanlẹnu fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu. Balogun ati aṣọle ikọ Tottenham, Hugo Lloris lo kọkọ tasẹ agẹrẹ bi Tacha lo ba mu bọọlu bọ sinu awọn ara rẹ. Laipẹ ni aṣọle fọwọ ṣeeṣe debi pe wọn ni lati gbe lọ sile iwosan lati ori papa. Ṣugbọn bi iya nla ba gbeni sanlẹ, kekere a gori ẹni ni Brighton fi ṣe fun Tottenham lẹyin ti wọn fi ọba lee pẹlu goolu meji. Lẹyin ọ rẹyin, Brighton ṣina iya fun Tottenham pẹlu ami ayo mẹta sodo lairo tẹlẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-49946254
2health
Ojisẹ Ọlọ́run fún osere tíátà ni ₦8m láti ṣiṣẹ abẹ
Yoruba ni ori ẹni nii gbe alawo rere ko ni, bi ori ba si pẹ nilẹ, yoo di ire ni. Bi ọrọ se jẹ ree pẹlu osere tiata kan, Clem Ohamese ẹni to ri aanu miliọnu mẹjọ naira gba lati ọwọ ojisẹ Ọlọrun kan. Bẹẹ ba gbagbe, BBC Yoruba ti kọkọ mu iroyin wa fun yin saaju nipa Ohamese to kede pe oun fẹ sisẹ abẹ nitori pe oun ko le rin daadaa. O ni ijamba ọkọ ti oun ni, lo ti se akoba fun awọn ọmọ ika ẹsẹ oun, tawọn dokita si ni oun nilo isẹ abẹ, ko to di pe oun yoo le rin daadaa. Ìdí sì rèé tí Clem Ohamese ṣe gbé fídíò kan síta pé òun fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ, kí àwọn èèyàn gbà àdúrà fún òun. Fídíò yìí ni ọkàn lára àwọn gbajugbaja ojisẹ Ọlọ́run kan, Wolii Jeremiah Omotofufeyin ri, to ṣe na ọwọ aanu si osere tiata naa. Wolii Omotofufeyin gbe ẹ̀bùn Milíọ̀nù mẹ́jọ náírà fún Clem Ohamese láti fi ṣiṣẹ abẹ ọhun. Ẹ̀bùn owó náà, to jẹ kikida beba sì ni wòlíì Omotofufeyin gbé kalẹ lásìkò ìsìn tó wáyé nínú ìjọ rẹ lọ́jọ́ Aiku níbi tó ti fún osere tíátà náà ni owo beba. Clem Ohameze, òṣèré tíátà ní àìlera, ó ń bẹ̀bẹ̀ àdúrà lórí iṣẹ́ abẹ O kere o pọ, ki Eleduwa ma jẹ ki aisan ṣe wa, ko ma ṣe ẹni ti a mọ. Gbajugbaja osẹre tiata Nollywood, Clem Ohameze lo n bẹbẹ adura lọwọ awọn ọmọ Naijiria bi o ti fẹ lọ fun iṣẹ abẹ ẹyin rẹ. Ohameze ṣalaye ninu fidio kan ti o fi si ori ayelujara, lo ti sọ pe oun fi eegun ẹyin ṣeṣe ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ si oun. O sọ pe ijamba ọkọ naa ti oun fi ẹyin ṣeṣe lawọn dokita sọ fun oun pe o ti ṣakoba fun ẹsẹ oun. Eyi ni ko le jẹ ki o le rin bayii, ṣugbọn pẹlu iṣẹ abẹ ti o fẹ ṣe, o yẹ ki ara rẹ le pada bọ sipo. Amọ, o sọ ninu fidio to fi lede lori ayelujara pe iṣẹ abẹ ọhun n ba oun lẹru. ''Mo nilo iranlọwọ awọn ọmọ Naijiria nipa adura bi mo ṣe n lọ fun iṣẹ abẹ yii. Ayẹwo ti wọn ṣe fun mi lẹyin ti ijamba ọkọ ṣẹlẹ si mi tan, lo fihan pe koko eegun kan ninu eegun ẹyin mi ti yẹ le omiran. Eleyii lo mu ki ẹru pọ lori eegun ẹyin mi ti ko si le jẹ ki n rin. Wọn tọju mi fun igba diẹ, mo gbadun diẹ, ṣugbọn laipẹ si akoko yii mo ṣe akiyesi pe mo n ni inira ti mo ba ti n rin. Mo pada lọ si ile iwosan nibi ti mo ti ṣe ayẹwo MRI lori ẹyin mi. Lẹyin ayẹwo yii ni awọn dokita sọ fun mi pe mo nilo iṣẹ abẹ lati ya koko eegun ẹyin mi meji to wa lori ara wọn ki n le maa rin daadaa. Ṣugbọn ẹru ba mi nigba ti wọn sọ fun mi ọna ti wọn maa n gba ṣe iṣẹ abẹ naa. Wọn ṣalaye fun mi pe wọn maa ni lati la ọrun mu lẹyin ki wọn lanfani lati ya koko egungun to sun lera wọn sọtọ. Amọ, bi ọjọ ṣe n gori ọjọ, mo ri pe ara inira naa n pọ si fun mi lati rin. Lẹyin naa ni mo pinnu lati ṣe iṣẹ abẹ ti wọn sọ yii ki n le maa rin pada. Ọkan mi daru gan an, ailera mi yii si ti ṣakoba iṣẹ mi ni gbogbo ọna. Loṣu to n bọ ni mo maa lọ fun iṣẹ abẹ yii, mo si mọ pe adura yii yoo gba lori mi, Ọlọrun yoo si ko mi yọ,'' Ohameze lo ṣalaye bẹẹ.
Ojisẹ Ọlọ́run fún osere tíátà ni ₦8m láti ṣiṣẹ abẹ Yoruba ni ori ẹni nii gbe alawo rere ko ni, bi ori ba si pẹ nilẹ, yoo di ire ni. Bi ọrọ se jẹ ree pẹlu osere tiata kan, Clem Ohamese ẹni to ri aanu miliọnu mẹjọ naira gba lati ọwọ ojisẹ Ọlọrun kan. Bẹẹ ba gbagbe, BBC Yoruba ti kọkọ mu iroyin wa fun yin saaju nipa Ohamese to kede pe oun fẹ sisẹ abẹ nitori pe oun ko le rin daadaa. O ni ijamba ọkọ ti oun ni, lo ti se akoba fun awọn ọmọ ika ẹsẹ oun, tawọn dokita si ni oun nilo isẹ abẹ, ko to di pe oun yoo le rin daadaa. Ìdí sì rèé tí Clem Ohamese ṣe gbé fídíò kan síta pé òun fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ, kí àwọn èèyàn gbà àdúrà fún òun. Fídíò yìí ni ọkàn lára àwọn gbajugbaja ojisẹ Ọlọ́run kan, Wolii Jeremiah Omotofufeyin ri, to ṣe na ọwọ aanu si osere tiata naa. Wolii Omotofufeyin gbe ẹ̀bùn Milíọ̀nù mẹ́jọ náírà fún Clem Ohamese láti fi ṣiṣẹ abẹ ọhun. Ẹ̀bùn owó náà, to jẹ kikida beba sì ni wòlíì Omotofufeyin gbé kalẹ lásìkò ìsìn tó wáyé nínú ìjọ rẹ lọ́jọ́ Aiku níbi tó ti fún osere tíátà náà ni owo beba. Clem Ohameze, òṣèré tíátà ní àìlera, ó ń bẹ̀bẹ̀ àdúrà lórí iṣẹ́ abẹ O kere o pọ, ki Eleduwa ma jẹ ki aisan ṣe wa, ko ma ṣe ẹni ti a mọ. Gbajugbaja osẹre tiata Nollywood, Clem Ohameze lo n bẹbẹ adura lọwọ awọn ọmọ Naijiria bi o ti fẹ lọ fun iṣẹ abẹ ẹyin rẹ. Ohameze ṣalaye ninu fidio kan ti o fi si ori ayelujara, lo ti sọ pe oun fi eegun ẹyin ṣeṣe ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ si oun. O sọ pe ijamba ọkọ naa ti oun fi ẹyin ṣeṣe lawọn dokita sọ fun oun pe o ti ṣakoba fun ẹsẹ oun. Eyi ni ko le jẹ ki o le rin bayii, ṣugbọn pẹlu iṣẹ abẹ ti o fẹ ṣe, o yẹ ki ara rẹ le pada bọ sipo. Amọ, o sọ ninu fidio to fi lede lori ayelujara pe iṣẹ abẹ ọhun n ba oun lẹru. ''Mo nilo iranlọwọ awọn ọmọ Naijiria nipa adura bi mo ṣe n lọ fun iṣẹ abẹ yii. Ayẹwo ti wọn ṣe fun mi lẹyin ti ijamba ọkọ ṣẹlẹ si mi tan, lo fihan pe koko eegun kan ninu eegun ẹyin mi ti yẹ le omiran. Eleyii lo mu ki ẹru pọ lori eegun ẹyin mi ti ko si le jẹ ki n rin. Wọn tọju mi fun igba diẹ, mo gbadun diẹ, ṣugbọn laipẹ si akoko yii mo ṣe akiyesi pe mo n ni inira ti mo ba ti n rin. Mo pada lọ si ile iwosan nibi ti mo ti ṣe ayẹwo MRI lori ẹyin mi. Lẹyin ayẹwo yii ni awọn dokita sọ fun mi pe mo nilo iṣẹ abẹ lati ya koko eegun ẹyin mi meji to wa lori ara wọn ki n le maa rin daadaa. Ṣugbọn ẹru ba mi nigba ti wọn sọ fun mi ọna ti wọn maa n gba ṣe iṣẹ abẹ naa. Wọn ṣalaye fun mi pe wọn maa ni lati la ọrun mu lẹyin ki wọn lanfani lati ya koko egungun to sun lera wọn sọtọ. Amọ, bi ọjọ ṣe n gori ọjọ, mo ri pe ara inira naa n pọ si fun mi lati rin. Lẹyin naa ni mo pinnu lati ṣe iṣẹ abẹ ti wọn sọ yii ki n le maa rin pada. Ọkan mi daru gan an, ailera mi yii si ti ṣakoba iṣẹ mi ni gbogbo ọna. Loṣu to n bọ ni mo maa lọ fun iṣẹ abẹ yii, mo si mọ pe adura yii yoo gba lori mi, Ọlọrun yoo si ko mi yọ,'' Ohameze lo ṣalaye bẹẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-59398770
2health
DR Congo Ebola: Òṣìṣẹ́ ìlera méje kú torí ibínú àwọn èèyàn nípa Ebola
''Awọn eniyan ro pe arun Ebola kii ṣe otitọ." Eyi ni ọrọ Dokita Pascal Vahwere, ọkan lara awọn dokita to n gbogun ti arun naa ni orilẹede Democratic Republic of Congo, DRC. "Ikọ̀ mi n f'oju wina ikọlu, nitori pe a n ṣe iṣẹ́ wa." Ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ eto ilera lo ti ku nitori pe wọn n tọju tabi polongo igbogun ti aarun Ebola ni orilẹede Democratic Republic of Congo. Ọkan lara awọn dokita to n ṣiṣẹ lati gbogun ti arun naa, Pascal Vahwere sọ iriri rẹ fun BBC lasiko ti awọn ara abule kan ni Ariwa ẹkùn Kivu deede yi oun ati ikọ rẹ ka lasiko ti wọn fẹ fun awọn ara abule naa ni abẹrẹ ajẹsara. "Lojiji ni awọn ero to ko ada ati ibọn dani yi wa ka. A ko mọ idi ti wọn fi fẹ ẹ ṣe ijamba fun wa. Ẹru ba wa. Nipasẹ awọn olori ilu la fi ba awọn ara ilu sọrọ, a si pẹtu si awọn ero naa l'ọkan." Bo ti lẹ jẹ pe itankalẹ arun Ebola n pa ọpọ eniyan si, sibẹ awọn oṣiṣẹ eto ilera n la ewu ibinu awọn ajijagbara ati eniyan miran kọja nitori awọn ayederu iroyin to n tan kalẹ bi ina inu ẹẹrun, paapa lori ayelujara Whatsapp. Ko din ni oṣiṣẹ eto ilera meje ti wọn ti pa ni ọdun yii nikan. BBC ba diẹ lara awọn to n gbogun ti Ebola sọrọ, lori idi ti eyi fi n ṣẹlẹ si wọn. Ayederu Iroyin "Awọn ayederu iroyin naa n mu ki awọn eniyan o ni igbagbọ pe, awọn oloṣelu n fi aarun Ebola pa owo si apo ara wọn." Dokita Vahwere, to sọ eyi fun BBC tun sọ pe "awọn miran tiẹ maa n sọ pe iwosan ti wọn n fun awọn to ni aarun naa gan an lo n pa wọn." Awọn ikọlu to ti waye: Awọn ayederu iroyin ti fa awọn ikọlu to l'agbara. Ọga agba ni ẹka ibanisọrọ ninu ajọ eleto ilera lagbaye WHO, sọ fun BBC pe: "laarin ọjọ kinni, oṣu Kinni si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje, ọdun 2019, ikọlu igba din meji ti ajọ eto ilera l'agbaye, WHO, ṣe akọsilẹ rẹ, fa iku oṣiṣẹ eto ilera meje, ti awọn mejidinlọgọta si fi ara pa ni orilẹede DRC." Itankalẹ aarun Ebola Bi awọn ikọlu naa ṣe n waye, to si n fa iku ọpọlọpọ ti mu ki adinku ba bi awọn oṣiṣẹ eto ilera ṣe n dena itankalẹ aarun naa ni DR Congo. Lai ti i pe ọdun kan, awọn to ti ni aarun naa ti pe ẹgbẹrun meji. Abẹrẹ Ajẹsara Wọn ti n fun awọn eniyan ni abẹrẹ ajẹsara kan ti wọn ṣẹṣẹ ṣe jade lati dena itankalẹ aarun Ebola. Awọn eniyan bi ẹgbẹrun lọna aadọsan to ti sunmọ awọn to ni aarun Ebola lo ti gba abẹrẹ ajẹsara naa. Ṣugbọn bi wọn ṣe n kọlu awọn oṣiṣẹ eto ilera ti fa idiwọ fun pinpin abẹrẹ naa, eyi si ti mu ki aarun naa tan kalẹ si. Ijọba orilẹede DR Congo n di ẹbi awọn ikọlu naa ru awọn oriṣiriṣi ikọ ajijagbara to wa ni orilẹede naa. Ṣugbọn kii ṣe awọn ajijagbara yii nikan lo n ṣe ikọlu, awọn araalu naa n kọlu awọn oṣiṣẹ eto ilera. Apẹẹrẹ iru iṣẹlẹ bẹẹ ni bi mọlẹbi ẹnikan ti arun naa pa, ṣe kọlu awọn oṣiṣẹ eto ilera to n bawọn mojuto isinku ẹbi wọn naa. Amọ ṣa, ijọba ti n fi awọn ọmọ ogun ṣọ diẹ lara awọn ile iwosan ti wọn ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ. Dokita Vahwere ti ẹ sọ pe, awọn eniyan kan ti n gbagbọ pe lootọ ni arun Ebola wa. "Ibẹru si ti n lọ lara awọn oṣiṣẹ eto ilera naa."
DR Congo Ebola: Òṣìṣẹ́ ìlera méje kú torí ibínú àwọn èèyàn nípa Ebola ''Awọn eniyan ro pe arun Ebola kii ṣe otitọ." Eyi ni ọrọ Dokita Pascal Vahwere, ọkan lara awọn dokita to n gbogun ti arun naa ni orilẹede Democratic Republic of Congo, DRC. "Ikọ̀ mi n f'oju wina ikọlu, nitori pe a n ṣe iṣẹ́ wa." Ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ eto ilera lo ti ku nitori pe wọn n tọju tabi polongo igbogun ti aarun Ebola ni orilẹede Democratic Republic of Congo. Ọkan lara awọn dokita to n ṣiṣẹ lati gbogun ti arun naa, Pascal Vahwere sọ iriri rẹ fun BBC lasiko ti awọn ara abule kan ni Ariwa ẹkùn Kivu deede yi oun ati ikọ rẹ ka lasiko ti wọn fẹ fun awọn ara abule naa ni abẹrẹ ajẹsara. "Lojiji ni awọn ero to ko ada ati ibọn dani yi wa ka. A ko mọ idi ti wọn fi fẹ ẹ ṣe ijamba fun wa. Ẹru ba wa. Nipasẹ awọn olori ilu la fi ba awọn ara ilu sọrọ, a si pẹtu si awọn ero naa l'ọkan." Bo ti lẹ jẹ pe itankalẹ arun Ebola n pa ọpọ eniyan si, sibẹ awọn oṣiṣẹ eto ilera n la ewu ibinu awọn ajijagbara ati eniyan miran kọja nitori awọn ayederu iroyin to n tan kalẹ bi ina inu ẹẹrun, paapa lori ayelujara Whatsapp. Ko din ni oṣiṣẹ eto ilera meje ti wọn ti pa ni ọdun yii nikan. BBC ba diẹ lara awọn to n gbogun ti Ebola sọrọ, lori idi ti eyi fi n ṣẹlẹ si wọn. Ayederu Iroyin "Awọn ayederu iroyin naa n mu ki awọn eniyan o ni igbagbọ pe, awọn oloṣelu n fi aarun Ebola pa owo si apo ara wọn." Dokita Vahwere, to sọ eyi fun BBC tun sọ pe "awọn miran tiẹ maa n sọ pe iwosan ti wọn n fun awọn to ni aarun naa gan an lo n pa wọn." Awọn ikọlu to ti waye: Awọn ayederu iroyin ti fa awọn ikọlu to l'agbara. Ọga agba ni ẹka ibanisọrọ ninu ajọ eleto ilera lagbaye WHO, sọ fun BBC pe: "laarin ọjọ kinni, oṣu Kinni si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje, ọdun 2019, ikọlu igba din meji ti ajọ eto ilera l'agbaye, WHO, ṣe akọsilẹ rẹ, fa iku oṣiṣẹ eto ilera meje, ti awọn mejidinlọgọta si fi ara pa ni orilẹede DRC." Itankalẹ aarun Ebola Bi awọn ikọlu naa ṣe n waye, to si n fa iku ọpọlọpọ ti mu ki adinku ba bi awọn oṣiṣẹ eto ilera ṣe n dena itankalẹ aarun naa ni DR Congo. Lai ti i pe ọdun kan, awọn to ti ni aarun naa ti pe ẹgbẹrun meji. Abẹrẹ Ajẹsara Wọn ti n fun awọn eniyan ni abẹrẹ ajẹsara kan ti wọn ṣẹṣẹ ṣe jade lati dena itankalẹ aarun Ebola. Awọn eniyan bi ẹgbẹrun lọna aadọsan to ti sunmọ awọn to ni aarun Ebola lo ti gba abẹrẹ ajẹsara naa. Ṣugbọn bi wọn ṣe n kọlu awọn oṣiṣẹ eto ilera ti fa idiwọ fun pinpin abẹrẹ naa, eyi si ti mu ki aarun naa tan kalẹ si. Ijọba orilẹede DR Congo n di ẹbi awọn ikọlu naa ru awọn oriṣiriṣi ikọ ajijagbara to wa ni orilẹede naa. Ṣugbọn kii ṣe awọn ajijagbara yii nikan lo n ṣe ikọlu, awọn araalu naa n kọlu awọn oṣiṣẹ eto ilera. Apẹẹrẹ iru iṣẹlẹ bẹẹ ni bi mọlẹbi ẹnikan ti arun naa pa, ṣe kọlu awọn oṣiṣẹ eto ilera to n bawọn mojuto isinku ẹbi wọn naa. Amọ ṣa, ijọba ti n fi awọn ọmọ ogun ṣọ diẹ lara awọn ile iwosan ti wọn ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ. Dokita Vahwere ti ẹ sọ pe, awọn eniyan kan ti n gbagbọ pe lootọ ni arun Ebola wa. "Ibẹru si ti n lọ lara awọn oṣiṣẹ eto ilera naa."
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49196385
4religion
Fake pastors: BBC Africa Eye díbọ́n bíi ọmọ ìjọ, àṣírí àwọn Pásítọ̀ èké nílẹ̀ yìí tú sí wa lọ́wọ́
Ayika ati ayida ilẹ Afirika gan ni ibudo ipawowọle wọn. Amọ bi awọn Pasitọ eke wọnyi ṣe n tan awọn ọmọ ijọ ati alatilẹyin wọn lati jere lara wọn ni ti owo, iyi ati agbara ti di ohun to mu kawọn eeyan ja fun ootọ ẹsin Kristẹni. Akọroyin ikọ Ọtẹlẹmuyẹ Africa Eye rinrinajo lọ si orilẹede Kenya lati lọ wadii awọn ijọ kan to ti sọ idile ati ọlọdani si ọwọ awọn adari ijọ eke. 'Gbogbo ìgbà ti mo bá rántí bí Táyà Tírélà ṣe gé ọwọ́ èmi àti ọmọ, ẹsẹ̀ rẹ̀ bàjẹ́, ojú mi fọ́..' Pásítọ̀ Olatokunbo Shonubi wọ gàù ní US lórí ẹ̀sùn ṣíṣe ayédèrú ìgbéyàwó 38 fáwọn àjèjì àti ọmọ onílùú Ọwọ́ tẹ 'pásítọ̀' tó ń ṣe ẹgbẹ́ òkùnkùn ní Bàrígà "Mo sá fún oògùn owó, igbó mímu, mo tún ní sùúrù fún ọdún 15 kí n tó di olókìkí" A máa ń lọ yọjú wo Yinka Quadri tó bá ń ṣe fíìmù ládùúgbò wa - Ẹ wo bí Dejo Tunfulu ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Tíátà 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí àpò owó “customer” tí mi ò mọwọ́
Fake pastors: BBC Africa Eye díbọ́n bíi ọmọ ìjọ, àṣírí àwọn Pásítọ̀ èké nílẹ̀ yìí tú sí wa lọ́wọ́ Ayika ati ayida ilẹ Afirika gan ni ibudo ipawowọle wọn. Amọ bi awọn Pasitọ eke wọnyi ṣe n tan awọn ọmọ ijọ ati alatilẹyin wọn lati jere lara wọn ni ti owo, iyi ati agbara ti di ohun to mu kawọn eeyan ja fun ootọ ẹsin Kristẹni. Akọroyin ikọ Ọtẹlẹmuyẹ Africa Eye rinrinajo lọ si orilẹede Kenya lati lọ wadii awọn ijọ kan to ti sọ idile ati ọlọdani si ọwọ awọn adari ijọ eke. 'Gbogbo ìgbà ti mo bá rántí bí Táyà Tírélà ṣe gé ọwọ́ èmi àti ọmọ, ẹsẹ̀ rẹ̀ bàjẹ́, ojú mi fọ́..' Pásítọ̀ Olatokunbo Shonubi wọ gàù ní US lórí ẹ̀sùn ṣíṣe ayédèrú ìgbéyàwó 38 fáwọn àjèjì àti ọmọ onílùú Ọwọ́ tẹ 'pásítọ̀' tó ń ṣe ẹgbẹ́ òkùnkùn ní Bàrígà "Mo sá fún oògùn owó, igbó mímu, mo tún ní sùúrù fún ọdún 15 kí n tó di olókìkí" A máa ń lọ yọjú wo Yinka Quadri tó bá ń ṣe fíìmù ládùúgbò wa - Ẹ wo bí Dejo Tunfulu ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Tíátà 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí àpò owó “customer” tí mi ò mọwọ́
https://www.bbc.com/yoruba/60987104
3politics
Diezani Alison-Madueke: Ìjọba lu kọ́mú, góòlù àti ilé mínísítà epo rọ̀bì tẹ́lẹ̀ Diezani ní gbàǹjo
Ijọba apapọ ti bẹrẹ si lu awọn dukia minisita eporọbi tẹlẹ ni Naijiria, Diezani Alison-Madueke ni gbanjo. Minisita epo rọbi tẹlẹ ọhun ti n jẹjọ lori ẹsun ṣiṣe owo ilu kumọ kumọ lasiko ijọba Aarẹ Goodluck Jonathan. Lara awọn dukia Diezani ti ijọba fẹ ta ni ile awo dami ẹnu to wa ni Banana Island lagbegbe Ikoyi niluu Eko. Awọn dukia Diezani ti ijọba tun fẹ ta ni goolu olowo iyebiye, aṣọ igbeyawo fun obinrin marunlelọgọfa, kootu mọkanla, kọmu mọkanla, iborun mẹtalelaadọrin. Awọn nkan mii ni faanu meji, aṣọ bẹẹdi mẹfa ati bata olowo iyebiye mẹrinlelọgọta. Bakan naa ni ijọba apapọ ti bẹrẹ idiyele dukia olori ileeṣẹ ọmogun ofurufu tẹlẹ ri, Air Chief Marshal Alex Badeh naa. Ijọba ti kọkọ gbẹsẹ le ile ọgagun Badeh to wa ni Wuse 2 ati Maitama lori ẹsun iwa ajẹbanu lẹnu iṣẹ ọba. Ni ọsẹ to lọ ni ijọba apapọ bẹrẹ ayẹwo fawọn onimọ nipa dukia tita to le ni ẹgbẹta lati ṣakoso tita awọn dukia tawọn oṣiṣẹ ọba ra lọna eeru. Awọn dukia naa to ti di ti ijọba lo wa ni agbegbe mẹẹdọgbọn kaakiri orilẹede Naijiria. Dukia bii ọkọ, ile, ẹrọ ibaraẹnisọrọ, ẹrọ kọmputa ati awọn nkan mii to jẹ 1,620 ni ijọba apapọ fẹ lu ni gbanjo. Ipinlẹ Eko ni awọn dukia yii pọ si julọ pẹlu ile mọkanlelọgbọn ati ọkọ 589. Alaga igbimọ to n ri si tita dukia ti ijọba ti gbẹsẹ le, Mohammed Etsu ṣalaye pe igbimọ naa yoo ri pe abo to muna doko wa lori awọn dukia naa. Diezani ti wa lorilẹede UK lati ọdun 2015 ti ijọba aarẹ Jonathan pari, lati igba naa si ni ko tii pada si Naijiria. Ẹwẹ, alaga ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu, Abdulrasheed Bawa, sọ loṣu Karun-un pe biliọnu mẹrinla Naira ni iye ti goolu Diezani to.
Diezani Alison-Madueke: Ìjọba lu kọ́mú, góòlù àti ilé mínísítà epo rọ̀bì tẹ́lẹ̀ Diezani ní gbàǹjo Ijọba apapọ ti bẹrẹ si lu awọn dukia minisita eporọbi tẹlẹ ni Naijiria, Diezani Alison-Madueke ni gbanjo. Minisita epo rọbi tẹlẹ ọhun ti n jẹjọ lori ẹsun ṣiṣe owo ilu kumọ kumọ lasiko ijọba Aarẹ Goodluck Jonathan. Lara awọn dukia Diezani ti ijọba fẹ ta ni ile awo dami ẹnu to wa ni Banana Island lagbegbe Ikoyi niluu Eko. Awọn dukia Diezani ti ijọba tun fẹ ta ni goolu olowo iyebiye, aṣọ igbeyawo fun obinrin marunlelọgọfa, kootu mọkanla, kọmu mọkanla, iborun mẹtalelaadọrin. Awọn nkan mii ni faanu meji, aṣọ bẹẹdi mẹfa ati bata olowo iyebiye mẹrinlelọgọta. Bakan naa ni ijọba apapọ ti bẹrẹ idiyele dukia olori ileeṣẹ ọmogun ofurufu tẹlẹ ri, Air Chief Marshal Alex Badeh naa. Ijọba ti kọkọ gbẹsẹ le ile ọgagun Badeh to wa ni Wuse 2 ati Maitama lori ẹsun iwa ajẹbanu lẹnu iṣẹ ọba. Ni ọsẹ to lọ ni ijọba apapọ bẹrẹ ayẹwo fawọn onimọ nipa dukia tita to le ni ẹgbẹta lati ṣakoso tita awọn dukia tawọn oṣiṣẹ ọba ra lọna eeru. Awọn dukia naa to ti di ti ijọba lo wa ni agbegbe mẹẹdọgbọn kaakiri orilẹede Naijiria. Dukia bii ọkọ, ile, ẹrọ ibaraẹnisọrọ, ẹrọ kọmputa ati awọn nkan mii to jẹ 1,620 ni ijọba apapọ fẹ lu ni gbanjo. Ipinlẹ Eko ni awọn dukia yii pọ si julọ pẹlu ile mọkanlelọgbọn ati ọkọ 589. Alaga igbimọ to n ri si tita dukia ti ijọba ti gbẹsẹ le, Mohammed Etsu ṣalaye pe igbimọ naa yoo ri pe abo to muna doko wa lori awọn dukia naa. Diezani ti wa lorilẹede UK lati ọdun 2015 ti ijọba aarẹ Jonathan pari, lati igba naa si ni ko tii pada si Naijiria. Ẹwẹ, alaga ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu, Abdulrasheed Bawa, sọ loṣu Karun-un pe biliọnu mẹrinla Naira ni iye ti goolu Diezani to.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-59060504
4religion
COZA: Mí o ba ijọ náà ṣe ìpolongo ètò wọ́n-Davido
Gbajúgbaja olórin tàkasúfèé David Adeleke ti gbogbo ènìyàn mọ si Davido ti gbarata lóri fọ́nran kan tó n tàn ka lori ayelujara lori oun ati COZA. Ori atẹjiṣẹ́ twitter rẹ lo ti yari lowurọ̀ oní (Ọjọbọ) pe irọ ni pe oun n polowo eto tuntun ti ijọ Commonwealth of Zion Assembly fẹ ṣe nibẹrẹ ọdun to n bọ. Fidio naa ṣafihan íbi ti Davido àti ọmọde kan ati obinrin kan ti jọ ń kéde èto ìsìn ọlọjọ mejila kan ti ijọ Common Wealth of Zion Assembly (COZA) fẹ́ ṣe loṣu to m bọ. Ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria jí lówurọ̀ òní ni wọn ba bẹ̀nu ẹ̀tẹ́ lú ìgbésẹ̀ Davido gẹ́gẹ́ bi wọ́n ṣe ri i nínú fọ́nran náà. Ṣugbọ́n bí Davido ṣe rii náà ni Davido ti kọ atẹjade kan lati tako fọ́nran náà pé òun kò ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú ìpolongo náà. O ni pé ọmọdebinrin to han nínú fọ́nran náà ni oun ṣe fidio náà fun nitori pe olólùfẹ́ òun ni kii ṣe ijọ COZA rara. Sùgbọ́n, kàkà ki ewé agbọ́n dẹ̀, o dàbi pé àtẹjade naa tún bẹ̀rẹ̀ si ni ru ọ̀rọ̀ míràn síta ni, ọ̀pọ̀ ni ojú kòró ni fọ́nran náà ati pe Davido kò sile so pe òun kò mọ ǹkan ti wọ́n fẹ́ fi ṣe. Nigba ti awọn miran kilọ iṣọra fawọn ijọ iwoyi pe ẹkọ gbigbona n fẹ suuru. Lẹ́yìn gbogbo ọhu-ọhu yìí ni obinrin tó farahàn nínú fọ́nran náà pada wá tọrọ aforijin lọ́wọ́ Davido ninu atẹjade to fi sita pe: Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Omalizz ni ni òun fẹ́ sàlàye ǹkan to ta kókó nínú fọ́nran náà. O ni òun ya fọ́nran ọhun pẹ̀lú Davido àti ọmọ òun fún ijọ oun tii ṣe COZA, o ní kìí ṣe ijọ lo ni fọ́nran náà wọ́n o si san owo fun Davido láti ṣe e sugbọ́n ona láti pe àkiyesi àwọn eniyan ni oun fi ṣe.
COZA: Mí o ba ijọ náà ṣe ìpolongo ètò wọ́n-Davido Gbajúgbaja olórin tàkasúfèé David Adeleke ti gbogbo ènìyàn mọ si Davido ti gbarata lóri fọ́nran kan tó n tàn ka lori ayelujara lori oun ati COZA. Ori atẹjiṣẹ́ twitter rẹ lo ti yari lowurọ̀ oní (Ọjọbọ) pe irọ ni pe oun n polowo eto tuntun ti ijọ Commonwealth of Zion Assembly fẹ ṣe nibẹrẹ ọdun to n bọ. Fidio naa ṣafihan íbi ti Davido àti ọmọde kan ati obinrin kan ti jọ ń kéde èto ìsìn ọlọjọ mejila kan ti ijọ Common Wealth of Zion Assembly (COZA) fẹ́ ṣe loṣu to m bọ. Ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria jí lówurọ̀ òní ni wọn ba bẹ̀nu ẹ̀tẹ́ lú ìgbésẹ̀ Davido gẹ́gẹ́ bi wọ́n ṣe ri i nínú fọ́nran náà. Ṣugbọ́n bí Davido ṣe rii náà ni Davido ti kọ atẹjade kan lati tako fọ́nran náà pé òun kò ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú ìpolongo náà. O ni pé ọmọdebinrin to han nínú fọ́nran náà ni oun ṣe fidio náà fun nitori pe olólùfẹ́ òun ni kii ṣe ijọ COZA rara. Sùgbọ́n, kàkà ki ewé agbọ́n dẹ̀, o dàbi pé àtẹjade naa tún bẹ̀rẹ̀ si ni ru ọ̀rọ̀ míràn síta ni, ọ̀pọ̀ ni ojú kòró ni fọ́nran náà ati pe Davido kò sile so pe òun kò mọ ǹkan ti wọ́n fẹ́ fi ṣe. Nigba ti awọn miran kilọ iṣọra fawọn ijọ iwoyi pe ẹkọ gbigbona n fẹ suuru. Lẹ́yìn gbogbo ọhu-ọhu yìí ni obinrin tó farahàn nínú fọ́nran náà pada wá tọrọ aforijin lọ́wọ́ Davido ninu atẹjade to fi sita pe: Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Omalizz ni ni òun fẹ́ sàlàye ǹkan to ta kókó nínú fọ́nran náà. O ni òun ya fọ́nran ọhun pẹ̀lú Davido àti ọmọ òun fún ijọ oun tii ṣe COZA, o ní kìí ṣe ijọ lo ni fọ́nran náà wọ́n o si san owo fun Davido láti ṣe e sugbọ́n ona láti pe àkiyesi àwọn eniyan ni oun fi ṣe.
https://www.bbc.com/yoruba/media-50848583
2health
Coronavirus cure: Akeugbagold sọ àṣírí ohun tí àrùn coronavirus ń dá lárà fáwọn pásítọ̀, àfáà àti ẹlẹ́sìn àbáláyé
Laipẹ yii ni eekan oniwaasi ni, Akeugbagold bọ lọwọ wahala awọn ajinigbepawo kan ti wọn ji awọn ọmọ rẹ gbe. Amọṣa ninu ifọrọwerọ yii pẹluu, kii ṣe ọrọ awọn ibeji rẹ ti wọn ji gbe lo ba BBC News Yoruba sọ bikoṣe ọwọja arun coronavirus to gbaye kan bayii ninu ilana ẹsin lagbaye. Gẹgẹbi o ṣe sọ, arun naa ti ṣi aṣọ loju ọpọ lati mọ Ọlọrun wn funrawọn.
Coronavirus cure: Akeugbagold sọ àṣírí ohun tí àrùn coronavirus ń dá lárà fáwọn pásítọ̀, àfáà àti ẹlẹ́sìn àbáláyé Laipẹ yii ni eekan oniwaasi ni, Akeugbagold bọ lọwọ wahala awọn ajinigbepawo kan ti wọn ji awọn ọmọ rẹ gbe. Amọṣa ninu ifọrọwerọ yii pẹluu, kii ṣe ọrọ awọn ibeji rẹ ti wọn ji gbe lo ba BBC News Yoruba sọ bikoṣe ọwọja arun coronavirus to gbaye kan bayii ninu ilana ẹsin lagbaye. Gẹgẹbi o ṣe sọ, arun naa ti ṣi aṣọ loju ọpọ lati mọ Ọlọrun wn funrawọn.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-52629093
5sports
Kashimawo Laloko: Gbajúgbajà akọ́nimọ̀ọ́gbá eré bọ́ọ̀lù Laloko tó ṣàwárí Mikel Obi àti Osaze dágbére fáyé
Iku ṣeka, iku doro. Iku ti mu ọga agba tẹrẹ ri ni ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba lorilẹede Naijiria, NFF, Kashimawo Laloko lọ. Ọkan lara awọn ọmọkunrin rẹ, Adewale lo kede pe ile iwosan Sacred Hearts Catholic Hospital niluu Abeokuta ni Laloko ku si lọjọ Aiku lẹni ọdun mẹrindinlọgọrin. Yatọ si wi pe, Laloko kii fọwọ sori ahọn sọ, o ṣiṣẹ takun takun lati mu ilọsiwaju ba gbajugbaja ileeṣẹ ikọni ni bọọlu afẹsẹgba Pepsi Football Academy. Ọpọ awọn agbabọọlu to di ilumọọka lonii lo jade lati Pepsi Football Academy. Awọn agbabọọlu bii Mikel Obi, Osaze Odemwingie, Soga Sambo, Elderson Echejile, Joseph Akpala ati Yinka Adedeji ati bẹẹ bẹẹ lọ lo jade ni Pepsi Academy. Koda Laloko ṣe akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Gambia nigba aye rẹ. Awọn ẹbi ti kede pe wọn yoo sin Laloko to jẹ Olori Parakoyi ilu Egba si ile rẹ to wa lagbegbe Gbonagun niluu Abeokuta.
Kashimawo Laloko: Gbajúgbajà akọ́nimọ̀ọ́gbá eré bọ́ọ̀lù Laloko tó ṣàwárí Mikel Obi àti Osaze dágbére fáyé Iku ṣeka, iku doro. Iku ti mu ọga agba tẹrẹ ri ni ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba lorilẹede Naijiria, NFF, Kashimawo Laloko lọ. Ọkan lara awọn ọmọkunrin rẹ, Adewale lo kede pe ile iwosan Sacred Hearts Catholic Hospital niluu Abeokuta ni Laloko ku si lọjọ Aiku lẹni ọdun mẹrindinlọgọrin. Yatọ si wi pe, Laloko kii fọwọ sori ahọn sọ, o ṣiṣẹ takun takun lati mu ilọsiwaju ba gbajugbaja ileeṣẹ ikọni ni bọọlu afẹsẹgba Pepsi Football Academy. Ọpọ awọn agbabọọlu to di ilumọọka lonii lo jade lati Pepsi Football Academy. Awọn agbabọọlu bii Mikel Obi, Osaze Odemwingie, Soga Sambo, Elderson Echejile, Joseph Akpala ati Yinka Adedeji ati bẹẹ bẹẹ lọ lo jade ni Pepsi Academy. Koda Laloko ṣe akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Gambia nigba aye rẹ. Awọn ẹbi ti kede pe wọn yoo sin Laloko to jẹ Olori Parakoyi ilu Egba si ile rẹ to wa lagbegbe Gbonagun niluu Abeokuta.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-56567788
5sports
Man Utd bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ lórí fífí òpin sí iṣẹ́ Ronaldo
Ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti bẹrẹ awọn igbesẹ labẹ ofin, eyi ti yoo fun wọn ni anfani lati fi opin si iwe adehun wọn pẹlu atamatase ọmọ ilẹ Portugal, Cristiano Ronaldo. O ti han gbangba pe Ronaldo ko ni le kopa mọ labẹ olukọni Erik ten Hag lẹyin to sọ awọn oko ọrọ kan ninu ifọrọwerọ kan to ṣe. Ronaldo si ni oṣu mejọ to ku ni ninu iwe adehun rẹ to kọwọ bọ pẹlu ikọ Manchester United. Manchester United ni anfani lati wogile iwe adehun pẹlu Ronaldo, eyi ti yoo fun ni anfani lati darapọ mọ ikọ agbabọọlu miiran to ba di ọdun to n bọ. Ifẹsẹwọnsẹ Manchester United pẹlu ikọ Aston Villa, nibi ti wọn ti fidi rẹmi ni ireti wa pe o le jẹ ifẹsẹwọnsẹ to kẹyin fun Ronaldo pẹlu ikọ Manchester United. Iroyin to tẹ wa lọwọ fi han pe awọn adari Manchester United ti bẹrẹ igbesẹ lori nkan ti wọn fẹ ṣe lori iwuwa si Ronaldo. Awọn adari ni igbagbọ wa pe wọn fẹ yanju ọrọ Ronaldo ki abale keji ligi saa yii to bẹrẹ ninu oṣu kini ọdun to n bọ. Kini Ronaldo sọ gan? Ronaldo, ninu ifọrọwerọ kan to ṣe ni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United da oun, ti oun ko si ni apọnle kankan fun olukọni Ten Hag. O ni wọn gbinyanju lati le oun kuro ninu ẹgbẹ agbabọọlu naa. Ifọrewerọ ọhun lo gba odi lara awọn adari ikọ Manchester United, ti wọn si bu ẹnu atẹlu iwa ati igbesẹ Ronaldo lori ọrọ naa. Ronaldo ni le waju ikọ agbabọọlu orilẹede Portugal lọ si orilẹede Qater nibi wọn yoo ti kopa ninu idije agbaye Fifa, eyi ti yoo bẹrẹ logunjọ oṣu yii. Atamatase agbawọwaju ikọ Manchester United, Cristiano Ronaldo ti darapọ mọ ikọ naa lẹyin ti akọnimọgba Erik Ten Hag palasẹ fun pe ko ma ṣe ìgbaradì fun ara rẹ. Ronaldo, ẹni ọdun metadinlogoji ni o kọ lati kopa ninu ifẹsẹwonsẹ to waye lọsẹ to kọja pelu ikọ Tottenham, ti wọn si yoo kuro ninu awọn agbabọọlu to irin irinajo lọ koju ikọ Chelsea ni opin ọsẹ. Ten Hag ni iwuwasi Ronaldo ni o ku diẹ kato, tí yoo si ri ijiya fun igbesẹ rẹ. A rí gbọ pe ọpọlọpọ gbolohun lọ tí waye laarin Ronaldo ati Ten Hag laarin ọjọ diẹ sẹyìn. Ronaldo ni orun to wa ni asiko naa  lo fa ti oun fi kuro lori paapa lọ yara imura níbi ifẹsẹwonsẹ pẹlu ikọ Tottenham. Ipadabọ Ronaldo ninu ikọ to n igbaradi lo sese ko fun ni anfani lati kopa ninu ifẹsẹwonsẹ iligi Uefa Europa níbi tí wọn yoo ti ma wa ko pẹlu ikọ agbabọọlu Sheriff Tiraspol lati orilẹede Moldova. Bakan an ni Balogun ikọ agbabọọluq Manchester United, Harry Maguire ati Donny Van de Beek naa kopa ninu igbaradi naa lẹyin ti wọn farapa. Ẹgbẹ agbabọọlu marun-un ni o ti peleke lọ ipele ẹlẹni mẹrindinlogun idije iligi Uefa Champion League sugbọn awọn wo ni yoo darapọ mọ wọn lalẹ oni Ikọ Manchester City ti bori awọn akẹgbẹ wọn sugbọn ikọ Liverpool, Chelsea ati Tottenham sini isẹ lati ṣe. Ikọ Liverpool nilo ami kan dondo lati pele sinu ipele ẹlẹni mẹrindinlogun ti wọn ba koju ikọ Ajax. Ajax ni lati borí ifẹsẹwonsẹ pẹlu ikọ Liverpool, tí wọn si ni lati gba ju ami ayo kan wọle. Tí Chelsea ba borí lalẹ oni, wọn yoo ni anfani lati kopa ninu ipele ẹlẹni mẹrindinlogun. Wó àwọn ifẹsẹwonsẹ tí yóò wáyé lálẹ́ òní: Salzburg v Chelsea Dinamo Zagreb v Milan Celtic v Shakhtar Donetsk RB Leipzig v Real Madrid Benfica v Juventus, Paris St-Germain v Maccabi Haifa Sevilla v Copenhagen Borussia Dortmund v Manchester City
Man Utd bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ lórí fífí òpin sí iṣẹ́ Ronaldo Ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti bẹrẹ awọn igbesẹ labẹ ofin, eyi ti yoo fun wọn ni anfani lati fi opin si iwe adehun wọn pẹlu atamatase ọmọ ilẹ Portugal, Cristiano Ronaldo. O ti han gbangba pe Ronaldo ko ni le kopa mọ labẹ olukọni Erik ten Hag lẹyin to sọ awọn oko ọrọ kan ninu ifọrọwerọ kan to ṣe. Ronaldo si ni oṣu mejọ to ku ni ninu iwe adehun rẹ to kọwọ bọ pẹlu ikọ Manchester United. Manchester United ni anfani lati wogile iwe adehun pẹlu Ronaldo, eyi ti yoo fun ni anfani lati darapọ mọ ikọ agbabọọlu miiran to ba di ọdun to n bọ. Ifẹsẹwọnsẹ Manchester United pẹlu ikọ Aston Villa, nibi ti wọn ti fidi rẹmi ni ireti wa pe o le jẹ ifẹsẹwọnsẹ to kẹyin fun Ronaldo pẹlu ikọ Manchester United. Iroyin to tẹ wa lọwọ fi han pe awọn adari Manchester United ti bẹrẹ igbesẹ lori nkan ti wọn fẹ ṣe lori iwuwa si Ronaldo. Awọn adari ni igbagbọ wa pe wọn fẹ yanju ọrọ Ronaldo ki abale keji ligi saa yii to bẹrẹ ninu oṣu kini ọdun to n bọ. Kini Ronaldo sọ gan? Ronaldo, ninu ifọrọwerọ kan to ṣe ni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United da oun, ti oun ko si ni apọnle kankan fun olukọni Ten Hag. O ni wọn gbinyanju lati le oun kuro ninu ẹgbẹ agbabọọlu naa. Ifọrewerọ ọhun lo gba odi lara awọn adari ikọ Manchester United, ti wọn si bu ẹnu atẹlu iwa ati igbesẹ Ronaldo lori ọrọ naa. Ronaldo ni le waju ikọ agbabọọlu orilẹede Portugal lọ si orilẹede Qater nibi wọn yoo ti kopa ninu idije agbaye Fifa, eyi ti yoo bẹrẹ logunjọ oṣu yii. Atamatase agbawọwaju ikọ Manchester United, Cristiano Ronaldo ti darapọ mọ ikọ naa lẹyin ti akọnimọgba Erik Ten Hag palasẹ fun pe ko ma ṣe ìgbaradì fun ara rẹ. Ronaldo, ẹni ọdun metadinlogoji ni o kọ lati kopa ninu ifẹsẹwonsẹ to waye lọsẹ to kọja pelu ikọ Tottenham, ti wọn si yoo kuro ninu awọn agbabọọlu to irin irinajo lọ koju ikọ Chelsea ni opin ọsẹ. Ten Hag ni iwuwasi Ronaldo ni o ku diẹ kato, tí yoo si ri ijiya fun igbesẹ rẹ. A rí gbọ pe ọpọlọpọ gbolohun lọ tí waye laarin Ronaldo ati Ten Hag laarin ọjọ diẹ sẹyìn. Ronaldo ni orun to wa ni asiko naa  lo fa ti oun fi kuro lori paapa lọ yara imura níbi ifẹsẹwonsẹ pẹlu ikọ Tottenham. Ipadabọ Ronaldo ninu ikọ to n igbaradi lo sese ko fun ni anfani lati kopa ninu ifẹsẹwonsẹ iligi Uefa Europa níbi tí wọn yoo ti ma wa ko pẹlu ikọ agbabọọlu Sheriff Tiraspol lati orilẹede Moldova. Bakan an ni Balogun ikọ agbabọọluq Manchester United, Harry Maguire ati Donny Van de Beek naa kopa ninu igbaradi naa lẹyin ti wọn farapa. Ẹgbẹ agbabọọlu marun-un ni o ti peleke lọ ipele ẹlẹni mẹrindinlogun idije iligi Uefa Champion League sugbọn awọn wo ni yoo darapọ mọ wọn lalẹ oni Ikọ Manchester City ti bori awọn akẹgbẹ wọn sugbọn ikọ Liverpool, Chelsea ati Tottenham sini isẹ lati ṣe. Ikọ Liverpool nilo ami kan dondo lati pele sinu ipele ẹlẹni mẹrindinlogun ti wọn ba koju ikọ Ajax. Ajax ni lati borí ifẹsẹwonsẹ pẹlu ikọ Liverpool, tí wọn si ni lati gba ju ami ayo kan wọle. Tí Chelsea ba borí lalẹ oni, wọn yoo ni anfani lati kopa ninu ipele ẹlẹni mẹrindinlogun. Wó àwọn ifẹsẹwonsẹ tí yóò wáyé lálẹ́ òní: Salzburg v Chelsea Dinamo Zagreb v Milan Celtic v Shakhtar Donetsk RB Leipzig v Real Madrid Benfica v Juventus, Paris St-Germain v Maccabi Haifa Sevilla v Copenhagen Borussia Dortmund v Manchester City
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cv29kx1zzy3o
3politics
Nnamdi Kanu IPOB case: Iléẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Nnamdi Kanu di oṣù kẹ̀wàà
Ileẹjọ kan ni ipinlẹ Abia ti sunjọ igbẹjọ ti Nnamdi Kanu gbe wa siwaju rẹ di ọjọ mii. Ẹjọ naa wa laarin ikọ ajijagbara Indigenous People of Biafra,IPOB ati awọn agbofinro Naijiria. Adajọ K.C.J. Okereke ti wọn gbẹjọ naa wa siwaju rẹ sunjọ igbẹjọ di ọjọ Kejej oṣu Kẹwa ọdun yi. Agbẹjọro agba Naijiria, ọga agba ileeṣẹ ọmọ ologun Naijiria ati ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa to fi mọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ni Kanu pe lẹjọ Ni nkan bi ago marun un aarọ lọj Iṣẹgun ni awọn agbofinro ti duro wauwamu lopopona Umuahia-Ikot Ekpene nibi ti ile ẹjọ giga to gbẹjọ naa wa. Awọn ọlọpaa gbegi dina ti eleyi si fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ. Toun ti ojo to rọ, awọn to ni nkan ṣe plu ẹjọ yi peju sile ẹjọ. Amọ ileẹj ko ribi gbẹjọ naa nitori awọn ti Kanu pe lẹjọ ''ko kọwe dahun ipẹjọ naa'' Adajọ gba gbogbo awọn ti ọrọ kan lati fesi si ọrọ to wa nilẹ ṣaaju ọjọ Keje oṣu Kẹwa. Eekan kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Jonathan Vatsa ti fi ero rẹ han pe o ṣeeṣe ki Nnamdi Kanu ati Sunday Igboho gba itusilẹ ti wọn ba darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC. Vatsa sọ eyi lasiko to n fi ero rẹ han lori bi minisita tẹlẹ feto irinna oju ofurufu, Femi Fani Kayode fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC. O ni Sunday Igboho ati Kanu yoo ri idariji gba, ti wọn ba darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ijọba apapọ nitori ọrọ wọn ko buru ju ti Fani-Kayode lọ. Ninu ọrọ rẹ, Vatsa ni ibaniloju jẹ gba a ni ki awọn ole ati ọlẹ ma a darapọ mọ ẹgbẹ APC nitori ohun ti wọn fẹ. Vatsa ni eleyii fihan pe ẹgbẹ oṣelu APC n tiraka lati gberi gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria. ''Ko ni ya mi lẹnu ti Igboho ati Kanu ba darapọ mọ APC lọna ati kuro ni panpẹ ati atimọle ti wọn wa. Eleyii safihan ilakaka ẹgbẹ oṣelu APC ati igbe aye ọbayegẹ ati ajẹbanu ti wọn n lo ninu ẹgbẹ oṣelu naa. Ole to ba ti darapọ mọ wọn bayii yoo gba itusilẹ ni, ti yoo si di eniyan nla ni awujọ. Awọn alajẹbanu, ti wọn ji owo Naijiria, ti wa di eekan ni ẹgbẹ oṣelu APC , o ti pari fun ẹgbẹ oṣelu APC, ko si afojusun fun ẹgbẹ naa.'' O ṣi n ya mi lẹnu bi Femi Fani-Kayode ṣe darapọ mọ ẹgbẹ APC ati bi wọn ṣe gba a wọle si ile aarẹ ni Aso Rock jẹ iyalẹnu gba a ni.'' Bakan naa, gbogbo awọn ọmọ Naijiria lo mọ iru iwa ajẹbanu ti Fani-Kayode hu lai yọ aarẹ Buhari silẹ pẹlu bi o ṣe na owo to yẹ ki wọn fi tun papakọ ofurufu ti ipinlẹ Port Harcourt, ti ko le ni biliọnu meji naira. Eekan ni ẹgbẹ oṣelu APC, Jonathan Vatsa lo fikun pe, Aarẹ Buhari naa sọ oju nu lori ẹsun ti wọn fi kan Fani-Kayode lori ipa to ko ninu iwa ajẹbanu ''Dasukigate''.
Nnamdi Kanu IPOB case: Iléẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Nnamdi Kanu di oṣù kẹ̀wàà Ileẹjọ kan ni ipinlẹ Abia ti sunjọ igbẹjọ ti Nnamdi Kanu gbe wa siwaju rẹ di ọjọ mii. Ẹjọ naa wa laarin ikọ ajijagbara Indigenous People of Biafra,IPOB ati awọn agbofinro Naijiria. Adajọ K.C.J. Okereke ti wọn gbẹjọ naa wa siwaju rẹ sunjọ igbẹjọ di ọjọ Kejej oṣu Kẹwa ọdun yi. Agbẹjọro agba Naijiria, ọga agba ileeṣẹ ọmọ ologun Naijiria ati ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa to fi mọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ni Kanu pe lẹjọ Ni nkan bi ago marun un aarọ lọj Iṣẹgun ni awọn agbofinro ti duro wauwamu lopopona Umuahia-Ikot Ekpene nibi ti ile ẹjọ giga to gbẹjọ naa wa. Awọn ọlọpaa gbegi dina ti eleyi si fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ. Toun ti ojo to rọ, awọn to ni nkan ṣe plu ẹjọ yi peju sile ẹjọ. Amọ ileẹj ko ribi gbẹjọ naa nitori awọn ti Kanu pe lẹjọ ''ko kọwe dahun ipẹjọ naa'' Adajọ gba gbogbo awọn ti ọrọ kan lati fesi si ọrọ to wa nilẹ ṣaaju ọjọ Keje oṣu Kẹwa. Eekan kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Jonathan Vatsa ti fi ero rẹ han pe o ṣeeṣe ki Nnamdi Kanu ati Sunday Igboho gba itusilẹ ti wọn ba darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC. Vatsa sọ eyi lasiko to n fi ero rẹ han lori bi minisita tẹlẹ feto irinna oju ofurufu, Femi Fani Kayode fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC. O ni Sunday Igboho ati Kanu yoo ri idariji gba, ti wọn ba darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ijọba apapọ nitori ọrọ wọn ko buru ju ti Fani-Kayode lọ. Ninu ọrọ rẹ, Vatsa ni ibaniloju jẹ gba a ni ki awọn ole ati ọlẹ ma a darapọ mọ ẹgbẹ APC nitori ohun ti wọn fẹ. Vatsa ni eleyii fihan pe ẹgbẹ oṣelu APC n tiraka lati gberi gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria. ''Ko ni ya mi lẹnu ti Igboho ati Kanu ba darapọ mọ APC lọna ati kuro ni panpẹ ati atimọle ti wọn wa. Eleyii safihan ilakaka ẹgbẹ oṣelu APC ati igbe aye ọbayegẹ ati ajẹbanu ti wọn n lo ninu ẹgbẹ oṣelu naa. Ole to ba ti darapọ mọ wọn bayii yoo gba itusilẹ ni, ti yoo si di eniyan nla ni awujọ. Awọn alajẹbanu, ti wọn ji owo Naijiria, ti wa di eekan ni ẹgbẹ oṣelu APC , o ti pari fun ẹgbẹ oṣelu APC, ko si afojusun fun ẹgbẹ naa.'' O ṣi n ya mi lẹnu bi Femi Fani-Kayode ṣe darapọ mọ ẹgbẹ APC ati bi wọn ṣe gba a wọle si ile aarẹ ni Aso Rock jẹ iyalẹnu gba a ni.'' Bakan naa, gbogbo awọn ọmọ Naijiria lo mọ iru iwa ajẹbanu ti Fani-Kayode hu lai yọ aarẹ Buhari silẹ pẹlu bi o ṣe na owo to yẹ ki wọn fi tun papakọ ofurufu ti ipinlẹ Port Harcourt, ti ko le ni biliọnu meji naira. Eekan ni ẹgbẹ oṣelu APC, Jonathan Vatsa lo fikun pe, Aarẹ Buhari naa sọ oju nu lori ẹsun ti wọn fi kan Fani-Kayode lori ipa to ko ninu iwa ajẹbanu ''Dasukigate''.
https://www.bbc.com/yoruba/58634909
4religion
Tope Ajogbajesu: Mọ̀lẹ́bí kan ní orin ikú ọdún yìí fò mí ru ní Tope kọ láàrin ọ̀sẹ̀ tó kú
Yoruba ni iku kii jẹ ki a dagbere fun ẹnikeji ẹni, ko to maa mu ni lọ. Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu iku gbajumọ akọrin ẹmi nni, Tope Ajogbajesu, ẹni ti yoo wọ kaa ilẹ sun lonii. BBC Yoruba se abẹwo si ile oloogbe naa, nibi ta ti ba aya rẹ, ibeji rẹ ati awọn mọlẹbi rẹ miran sọrọ lori ipa ti iku rẹ yoo ni lara wọn. Aya oloogbe naa ni aisan ọgbẹ inu, taa mọ si Ulcer lo mu Tope ni oru Ọjọbọ, to si ku ni ọjọ Ẹti, bẹẹ lo yẹ ko gba ami ẹyẹ kan ni ọjọ Sunday. O ni aisan ọgbẹ inu naa ti n yọ ọkọ oun lẹnu, ọjọ ti pẹ amọ oun dupẹ pe inu ifẹ Kristi ni ọkọ oun ku si, ti ko si jẹ ki Jesu bọ lọwọ oun. Nigba toun naa n sọrọ, ikeji Tope Ajogbajesu ni oro ati ọgbẹ ọkan nla ni iku ẹnikeji oun fun oun nitori inu ifẹ nla ni awọn dijọ n gbe. Mọlẹbi kan wa salaye pe isin kan ti Tope lọ ni ọsẹ to ku lo ti n kọrin pe iku ọdun yii fo oun ru laimọ pe ọsẹ naa ni yoo ku.
Tope Ajogbajesu: Mọ̀lẹ́bí kan ní orin ikú ọdún yìí fò mí ru ní Tope kọ láàrin ọ̀sẹ̀ tó kú Yoruba ni iku kii jẹ ki a dagbere fun ẹnikeji ẹni, ko to maa mu ni lọ. Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu iku gbajumọ akọrin ẹmi nni, Tope Ajogbajesu, ẹni ti yoo wọ kaa ilẹ sun lonii. BBC Yoruba se abẹwo si ile oloogbe naa, nibi ta ti ba aya rẹ, ibeji rẹ ati awọn mọlẹbi rẹ miran sọrọ lori ipa ti iku rẹ yoo ni lara wọn. Aya oloogbe naa ni aisan ọgbẹ inu, taa mọ si Ulcer lo mu Tope ni oru Ọjọbọ, to si ku ni ọjọ Ẹti, bẹẹ lo yẹ ko gba ami ẹyẹ kan ni ọjọ Sunday. O ni aisan ọgbẹ inu naa ti n yọ ọkọ oun lẹnu, ọjọ ti pẹ amọ oun dupẹ pe inu ifẹ Kristi ni ọkọ oun ku si, ti ko si jẹ ki Jesu bọ lọwọ oun. Nigba toun naa n sọrọ, ikeji Tope Ajogbajesu ni oro ati ọgbẹ ọkan nla ni iku ẹnikeji oun fun oun nitori inu ifẹ nla ni awọn dijọ n gbe. Mọlẹbi kan wa salaye pe isin kan ti Tope lọ ni ọsẹ to ku lo ti n kọrin pe iku ọdun yii fo oun ru laimọ pe ọsẹ naa ni yoo ku.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58156116
3politics
Alao Akala: Àwa àti ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo la jọ ń ṣèpàdé, ohun tí mọ̀lẹ́bí sọ gangan rè
Ẹbi gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ to ṣalaisi, oloogbe Otunba Adebayo Alao-Akala ti ni iroyin eto bi isinku oloogbe naa yoo ṣe waye to gba ori ayelujara kan kii ṣe ọwọ awọn lo ti wa pe ahesọ ọrọ lasan ni. Ninu ọrọ kan ti agbẹnusọ mọlẹbi naa, Tolu Mustapha fi sita, o fihan pe digbi ni ijọba ipinlẹ naa n da si bi gbogbo eto isinku naa yoo ṣe lọ. O sọ eyi ninu atẹjade kan ni ọjọ Iṣẹgun wipe ifọrọjomitoro ọrọ ṣi n waye lori ọna ti wọn yoo gba ṣe eto isinku naa. Ẹlẹ́ṣin tó gbé òkú Ọba Wukari pọ̀n wọ inú igbó rèé o! Ó sọ ìrírí rẹ ó sì tún já irọ ìròyìn orí ayélujára nípa rẹ̀ Wo àwọn ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Alao Akala tó dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 71 Háà, nǹkan ṣe mí! Ikú pa ọ̀kan lára àwọn aláànú mi - Yinka Ayefele Atẹ́jade naa ka bayii pe: Gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri, Otunba Adebayo Alao-Akala yoo gba eto isinku to ni iyi latọd ijọba ipinlẹ tori naa, ijọba n lọwọ si gbogbo eto isinku rẹ. ifọrọjomitoro ọrọ ṣi n lọ lọwọ a o si fi gbogbo eto ti a ba la kalẹ fun eto isinku to ni iyi to gbogbo ara ilu leti bi asiko ba ti to". O ni "mo fi n daa yin loju pe wọn yoo bu ọla fun Otuna jake jado ipinlẹ Oyo". Ẹwẹ, awọn iroyin kan ti n jade to n sọ pe wọn ti dajọ eto isinku fun gomina Oyo tẹlẹ yii si ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹẹdogun ati ọjọ Ẹti ọjọ kejidinlogun oṣu Keji ọdun 2022. Amọ o ni ko sohun to jọ bẹẹ to jade wa lati ọdọ awọn. Ẹ o ranti pe Alao-Akala dagbere faye ni owurọ Ọjọru ọjọ Kejila oṣu Kinni ọdun 2022 ni ile rẹ to wa ni ilu rẹ, Ogbomoso. Ọlọ́run Tinubu kìí ṣé Ọlọ́run témi torínáà mi o ní gbè lẹyìn rẹ̀ ní 2023- Ojudu Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ lónìí lórí ọ̀rọ̀ Kanu lẹ́yìn tó sọ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án Pẹ̀lú bí Dayo Kujore ṣe fi ayé rẹ̀ sin Nàìjíríà tó, kò sí ẹnìkan tó bá wa kẹ́dùn lẹ́yìn ikú rẹ̀- Ayinke Kujore 'Ìwọ tóo bá ní Sabuké ìwé mẹ́wàá, kò yẹ kóò súnmọ́ dídu ipò òṣèlú kankan' Ǹjẹ́ obìnrin leè di "virgin" padà bí kò bá ní ìbálòpọ̀ fún ìgbá pípẹ́? - Onímọ̀ nípa ìbálòpọ̀ bá BBC sọ̀rọ̀
Alao Akala: Àwa àti ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo la jọ ń ṣèpàdé, ohun tí mọ̀lẹ́bí sọ gangan rè Ẹbi gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ to ṣalaisi, oloogbe Otunba Adebayo Alao-Akala ti ni iroyin eto bi isinku oloogbe naa yoo ṣe waye to gba ori ayelujara kan kii ṣe ọwọ awọn lo ti wa pe ahesọ ọrọ lasan ni. Ninu ọrọ kan ti agbẹnusọ mọlẹbi naa, Tolu Mustapha fi sita, o fihan pe digbi ni ijọba ipinlẹ naa n da si bi gbogbo eto isinku naa yoo ṣe lọ. O sọ eyi ninu atẹjade kan ni ọjọ Iṣẹgun wipe ifọrọjomitoro ọrọ ṣi n waye lori ọna ti wọn yoo gba ṣe eto isinku naa. Ẹlẹ́ṣin tó gbé òkú Ọba Wukari pọ̀n wọ inú igbó rèé o! Ó sọ ìrírí rẹ ó sì tún já irọ ìròyìn orí ayélujára nípa rẹ̀ Wo àwọn ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Alao Akala tó dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 71 Háà, nǹkan ṣe mí! Ikú pa ọ̀kan lára àwọn aláànú mi - Yinka Ayefele Atẹ́jade naa ka bayii pe: Gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri, Otunba Adebayo Alao-Akala yoo gba eto isinku to ni iyi latọd ijọba ipinlẹ tori naa, ijọba n lọwọ si gbogbo eto isinku rẹ. ifọrọjomitoro ọrọ ṣi n lọ lọwọ a o si fi gbogbo eto ti a ba la kalẹ fun eto isinku to ni iyi to gbogbo ara ilu leti bi asiko ba ti to". O ni "mo fi n daa yin loju pe wọn yoo bu ọla fun Otuna jake jado ipinlẹ Oyo". Ẹwẹ, awọn iroyin kan ti n jade to n sọ pe wọn ti dajọ eto isinku fun gomina Oyo tẹlẹ yii si ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹẹdogun ati ọjọ Ẹti ọjọ kejidinlogun oṣu Keji ọdun 2022. Amọ o ni ko sohun to jọ bẹẹ to jade wa lati ọdọ awọn. Ẹ o ranti pe Alao-Akala dagbere faye ni owurọ Ọjọru ọjọ Kejila oṣu Kinni ọdun 2022 ni ile rẹ to wa ni ilu rẹ, Ogbomoso. Ọlọ́run Tinubu kìí ṣé Ọlọ́run témi torínáà mi o ní gbè lẹyìn rẹ̀ ní 2023- Ojudu Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ lónìí lórí ọ̀rọ̀ Kanu lẹ́yìn tó sọ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án Pẹ̀lú bí Dayo Kujore ṣe fi ayé rẹ̀ sin Nàìjíríà tó, kò sí ẹnìkan tó bá wa kẹ́dùn lẹ́yìn ikú rẹ̀- Ayinke Kujore 'Ìwọ tóo bá ní Sabuké ìwé mẹ́wàá, kò yẹ kóò súnmọ́ dídu ipò òṣèlú kankan' Ǹjẹ́ obìnrin leè di "virgin" padà bí kò bá ní ìbálòpọ̀ fún ìgbá pípẹ́? - Onímọ̀ nípa ìbálòpọ̀ bá BBC sọ̀rọ̀
https://www.bbc.com/yoruba/60042999
3politics
APC Oyo Primaries: Àwọn aṣaájú ké gbàjaré pé ìbò abẹ́nú APC Oyo tó kọjá mẹ́hẹ
Ipade idibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo waye ni ọjọ Satide, tawọn ọmọ igbimọ alasẹ ẹgbẹ tuntun si fi oju han. Amọ sibẹ, ọrọ si ku lori abọ ipade idibo abẹnu naa nitori awọn igun kan ninu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo ti n fi apa janu, ti wọn si kọ esi idibo ọhun. Alaga ẹgbẹ oṣelu naa to n fi ipo silẹ, Oloye Akin Ọkẹ ṣalaye pe itọsẹ lo lọyọ, o ye ki wọn ṣe ohun gbogbo bo ṣe tọ. Oloye Ọkẹ ni aifẹ tẹle ilana tawọn babanla ẹgbẹ naa fi lelẹ ni ipilẹ ẹgbẹ oṣelu naa, lo n fa gbogbo dukuu laarin ẹgbẹ naa. O ni ohun to ku diẹ kaato ni lati rii pe awọn eeyan kan lẹgbẹ oṣelu APC gbimọ pọ lati mu ayederu orukọ wọ inu iwe orukọ awọn aṣoju idibo to yẹ ko farahan nibi ipade idibo yan adari, congress, to waye ni ipinlẹ Ọyọ. O ni gbogbo awọn to wa gẹgẹ bi ọmọ igbimọ kokari eto idibo naa ni wọn fọwọsi pe ki wọn ṣe ohun gbogbo bo ṣe tọ. O fi kun pe ibẹru awọn eekan ẹgbẹ naa gbogbo ṣaaju eto idibo naa ni pe, awọn eeyan kan ti tọwọ bọ iwe orukọ awọn aṣojudibo l'Eko ati l'Abuja. O ni bo tilẹ jẹ pe awọn awọn aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu naa ko gba eyi gbọ nigba naa, eleyi to mu ki wọn beere fun iwe orukọ ti wọn yoo lo fun idibo naa lọjọ Ẹti. Amọṣa, iyalẹnu lo jẹ lati rii pe ọpọ asawọ lo ti wọ inu iwe orukọ naa, gẹgẹ bi Oloye Akin Ọkẹ ṣe sọ fun BBC News Yoruba. Ẹwẹ, minisita fun ere idaraya, Sunday Dare ti oun pẹlu ti fi ẹhonu han lori igbesẹ naa ni awọn eeyan perete kan ni wọn fẹ fi tipatipa ja ẹgbẹ oṣelu naa gba mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lọwọ ni ipinlẹ Ọyọ. Ninu atẹjade kan to n lọ kaakiri awọn iwe iroyin abẹle ni Naijiria, Sunday Dare ṣalaye pe awọn to wa nidi eto naa n wa ọna lati tu ẹgbẹ naa ka ni. Igbesẹ awọn iwọnba perete lati ja ẹgbẹ oṣelu yii gba ko ni jọ. Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lo duro lori idagbasoke rẹ. Lara awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu naa to n tako eto naa bayii ni alaga ajọ feto ibaraẹnisọrọ (NCC), Ọjọgbọn Adeolu Akande ati oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC nigba kan ri, Oloye Olasunkanmi Tegbe. Awọn yoku ni oludije gomina to kọja nipinlẹ Ọyọ, Oloye Adebayo Adelabu; Olagunju Ojo; Fatai Ibikunle ati Ọmọọba Ayodeji Abass-Aleshinloye. Awọn yoku ni Oloye Sarafadeen Alli, to figbakan ri jẹ akọwe ijọba ipinlẹ Oyo atawọn eekan ẹgbẹ APC miran. Amọṣa, nigba ti BBC News Yoruba kan si awọn ọmọ igbimọ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan naa, Ọgbẹni Mojeed Ọlaọya, ti wọn ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bii alaga fun ẹkun idibo gusu ipinlẹ Ọyọ ṣalaye pe ko si kalọkabọ kankan lori ọrọ yii. O ni ohun ti awọn n fẹ ni pe ki igbimọ apapọ ẹgbẹ naa da si aawọ naa lọ, igbesẹ wọn si lawọn n reti lọwọ. Amọṣa, alaga to n fipo silẹ lẹgbẹ oṣelu naa, Oloye Akin Ọkẹ rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ lati ṣe suuru, ki wọn fi wa ojuutu si ọrọ ọhun. Bakan naa lo ke si Ọgbẹni Ọmọdewu ti wọn ṣẹṣẹ kede gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oṣelu naa, lati ṣe pẹlẹ ko si duro naa "nitori nigba ti alaafia ba wa leyan lee sọ pe oun n ṣe alaga." Ipade idibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo waye ni ọjọ Satide, tawọn ọmọ igbimọ alasẹ ẹgbẹ tuntun si fi oju han. Amọ sibẹ, ọrọ si ku lori abọ ipade idibo abẹnu naa nitori awọn igun kan ninu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo ti n fi apa janu, ti wọn si kọ esi idibo ọhun. Ipade idibo naa, ti Gambo Lawan se alaga fun lo waye ni papa Liberty nilu Ibadan, ti iroyin si ni awọn janduku kan tilẹkun mọ alaga naa lati aago meje aarọ, ti ko si le peju sibi ti ipade ọhun ti waye. Awọn janduku naa si lo sọ fun Gambo pe ko ni ri ọna lọ ayafi to ba kede pe oun ti wọgile idibo abẹnu naa, ti ko si ni waye mọ. Koda, ni ibẹrẹ eto naa ni awọn igun kan ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Oyo ti ni ki wọn wọgile idibo abẹnu naa nitori oniruuru orukọ awọn oludibo to jẹ ayederu lo ti jade sita. Igba keji si ree ti wọn yoo sun eto idibo naa siwaju, ti wahala si tun fẹ bẹ silẹ ni igba kẹta. Awọn igun to n fi apa janu naa, ti wọn tilẹkun mọ Gambo lati jẹ ko ri ọna de ibi ipade naa ni ko mọ pe akọwe igbimọ to n se kokari ibo ọhun, atawọn ọmọ igbimọ naa kan, ti de ibudo ti idibo naa yoo ti waye. Nigba to n fi idi isẹlẹ yii mulẹ lori eto ori redio kan nilu Ibadan, Gambo ni o ya oun lẹnu pe awọn eekan kan ninu ẹgbẹ oselu naa le ran awọn janduku lati wa fa ọwọ aago ibo naa sẹyin. A gbọ pe gbogbo aayan gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, Adebayo Alao Akala lati yọ Gambo ninu ahamọ tipa ti wọn fi si naa lo ja si pabo. Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa, Civil Defence ati DSS lo jẹ ki Gambo gba idande ni aago meje alẹ lẹyin ti idibo ti pari tan. Amọ lẹyin abọ idibo to waye lasiko ipade apapọ ẹgbẹ APC naa, Isaac Omodewu, tii se Kọmisana tẹlẹ labẹ ijọba Ajimobi ni wọn kede pe o jawe olubori bii alaga ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo. Ninu ọrọ akọsọ rẹ, Omodewu rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa lati gba alafia laaye, ki wọn fi ọwọ wọnu, ki wọn si pa imọ pọ lati mu ki ẹgbẹ naa de ibi giga. O wa dupẹ lọwọ awọn asaaju ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo fun atilẹyin wọn, to si fi ọwọ gbaya pe oun yoo pari ija laarin awọn ọmọ ẹgbẹ to n fi apa janu. Awọn igun ti Unity Forum, Ajimobi Legacy, Zenity Labour Party ati Oloye Adeniyi Akintola si lo ti ki alaga tuntun fun ẹgbẹ naa ku oriire. Atẹjade kan ti Sẹnatọ Ayoade Adeseun, Oloye Sarafa Alli, Amofin Ayo Ojeniyi ati Asofin Tolu Sadipe dijọ fi ọwọ si wa kan saara si awọn ọmọ ẹgbẹ naa fun bi wọn se se ojuse wọn nilana isejọba awa ara wa. Bakan naa ni wọn yonbo wọn fun bi wsn ko se gba ki alaga ipade idibo abẹnu naa dari idibo mọkaruru, eyi to mu mẹrin ninu awọn ọmọ igbimọ alako ipade naa kọwe fipo silẹ. Wayi o, awọn igun ẹgbẹ oselu APC ti inu n bi ti n fi apa janu lori esi idibo abẹnu naa nibi ti Isaac Omodewu ti jawe olubori bii alaga ẹgbẹ.
APC Oyo Primaries: Àwọn aṣaájú ké gbàjaré pé ìbò abẹ́nú APC Oyo tó kọjá mẹ́hẹ Ipade idibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo waye ni ọjọ Satide, tawọn ọmọ igbimọ alasẹ ẹgbẹ tuntun si fi oju han. Amọ sibẹ, ọrọ si ku lori abọ ipade idibo abẹnu naa nitori awọn igun kan ninu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo ti n fi apa janu, ti wọn si kọ esi idibo ọhun. Alaga ẹgbẹ oṣelu naa to n fi ipo silẹ, Oloye Akin Ọkẹ ṣalaye pe itọsẹ lo lọyọ, o ye ki wọn ṣe ohun gbogbo bo ṣe tọ. Oloye Ọkẹ ni aifẹ tẹle ilana tawọn babanla ẹgbẹ naa fi lelẹ ni ipilẹ ẹgbẹ oṣelu naa, lo n fa gbogbo dukuu laarin ẹgbẹ naa. O ni ohun to ku diẹ kaato ni lati rii pe awọn eeyan kan lẹgbẹ oṣelu APC gbimọ pọ lati mu ayederu orukọ wọ inu iwe orukọ awọn aṣoju idibo to yẹ ko farahan nibi ipade idibo yan adari, congress, to waye ni ipinlẹ Ọyọ. O ni gbogbo awọn to wa gẹgẹ bi ọmọ igbimọ kokari eto idibo naa ni wọn fọwọsi pe ki wọn ṣe ohun gbogbo bo ṣe tọ. O fi kun pe ibẹru awọn eekan ẹgbẹ naa gbogbo ṣaaju eto idibo naa ni pe, awọn eeyan kan ti tọwọ bọ iwe orukọ awọn aṣojudibo l'Eko ati l'Abuja. O ni bo tilẹ jẹ pe awọn awọn aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu naa ko gba eyi gbọ nigba naa, eleyi to mu ki wọn beere fun iwe orukọ ti wọn yoo lo fun idibo naa lọjọ Ẹti. Amọṣa, iyalẹnu lo jẹ lati rii pe ọpọ asawọ lo ti wọ inu iwe orukọ naa, gẹgẹ bi Oloye Akin Ọkẹ ṣe sọ fun BBC News Yoruba. Ẹwẹ, minisita fun ere idaraya, Sunday Dare ti oun pẹlu ti fi ẹhonu han lori igbesẹ naa ni awọn eeyan perete kan ni wọn fẹ fi tipatipa ja ẹgbẹ oṣelu naa gba mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lọwọ ni ipinlẹ Ọyọ. Ninu atẹjade kan to n lọ kaakiri awọn iwe iroyin abẹle ni Naijiria, Sunday Dare ṣalaye pe awọn to wa nidi eto naa n wa ọna lati tu ẹgbẹ naa ka ni. Igbesẹ awọn iwọnba perete lati ja ẹgbẹ oṣelu yii gba ko ni jọ. Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lo duro lori idagbasoke rẹ. Lara awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu naa to n tako eto naa bayii ni alaga ajọ feto ibaraẹnisọrọ (NCC), Ọjọgbọn Adeolu Akande ati oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC nigba kan ri, Oloye Olasunkanmi Tegbe. Awọn yoku ni oludije gomina to kọja nipinlẹ Ọyọ, Oloye Adebayo Adelabu; Olagunju Ojo; Fatai Ibikunle ati Ọmọọba Ayodeji Abass-Aleshinloye. Awọn yoku ni Oloye Sarafadeen Alli, to figbakan ri jẹ akọwe ijọba ipinlẹ Oyo atawọn eekan ẹgbẹ APC miran. Amọṣa, nigba ti BBC News Yoruba kan si awọn ọmọ igbimọ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan naa, Ọgbẹni Mojeed Ọlaọya, ti wọn ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bii alaga fun ẹkun idibo gusu ipinlẹ Ọyọ ṣalaye pe ko si kalọkabọ kankan lori ọrọ yii. O ni ohun ti awọn n fẹ ni pe ki igbimọ apapọ ẹgbẹ naa da si aawọ naa lọ, igbesẹ wọn si lawọn n reti lọwọ. Amọṣa, alaga to n fipo silẹ lẹgbẹ oṣelu naa, Oloye Akin Ọkẹ rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ lati ṣe suuru, ki wọn fi wa ojuutu si ọrọ ọhun. Bakan naa lo ke si Ọgbẹni Ọmọdewu ti wọn ṣẹṣẹ kede gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oṣelu naa, lati ṣe pẹlẹ ko si duro naa "nitori nigba ti alaafia ba wa leyan lee sọ pe oun n ṣe alaga." Ipade idibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo waye ni ọjọ Satide, tawọn ọmọ igbimọ alasẹ ẹgbẹ tuntun si fi oju han. Amọ sibẹ, ọrọ si ku lori abọ ipade idibo abẹnu naa nitori awọn igun kan ninu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo ti n fi apa janu, ti wọn si kọ esi idibo ọhun. Ipade idibo naa, ti Gambo Lawan se alaga fun lo waye ni papa Liberty nilu Ibadan, ti iroyin si ni awọn janduku kan tilẹkun mọ alaga naa lati aago meje aarọ, ti ko si le peju sibi ti ipade ọhun ti waye. Awọn janduku naa si lo sọ fun Gambo pe ko ni ri ọna lọ ayafi to ba kede pe oun ti wọgile idibo abẹnu naa, ti ko si ni waye mọ. Koda, ni ibẹrẹ eto naa ni awọn igun kan ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Oyo ti ni ki wọn wọgile idibo abẹnu naa nitori oniruuru orukọ awọn oludibo to jẹ ayederu lo ti jade sita. Igba keji si ree ti wọn yoo sun eto idibo naa siwaju, ti wahala si tun fẹ bẹ silẹ ni igba kẹta. Awọn igun to n fi apa janu naa, ti wọn tilẹkun mọ Gambo lati jẹ ko ri ọna de ibi ipade naa ni ko mọ pe akọwe igbimọ to n se kokari ibo ọhun, atawọn ọmọ igbimọ naa kan, ti de ibudo ti idibo naa yoo ti waye. Nigba to n fi idi isẹlẹ yii mulẹ lori eto ori redio kan nilu Ibadan, Gambo ni o ya oun lẹnu pe awọn eekan kan ninu ẹgbẹ oselu naa le ran awọn janduku lati wa fa ọwọ aago ibo naa sẹyin. A gbọ pe gbogbo aayan gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, Adebayo Alao Akala lati yọ Gambo ninu ahamọ tipa ti wọn fi si naa lo ja si pabo. Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa, Civil Defence ati DSS lo jẹ ki Gambo gba idande ni aago meje alẹ lẹyin ti idibo ti pari tan. Amọ lẹyin abọ idibo to waye lasiko ipade apapọ ẹgbẹ APC naa, Isaac Omodewu, tii se Kọmisana tẹlẹ labẹ ijọba Ajimobi ni wọn kede pe o jawe olubori bii alaga ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo. Ninu ọrọ akọsọ rẹ, Omodewu rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa lati gba alafia laaye, ki wọn fi ọwọ wọnu, ki wọn si pa imọ pọ lati mu ki ẹgbẹ naa de ibi giga. O wa dupẹ lọwọ awọn asaaju ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo fun atilẹyin wọn, to si fi ọwọ gbaya pe oun yoo pari ija laarin awọn ọmọ ẹgbẹ to n fi apa janu. Awọn igun ti Unity Forum, Ajimobi Legacy, Zenity Labour Party ati Oloye Adeniyi Akintola si lo ti ki alaga tuntun fun ẹgbẹ naa ku oriire. Atẹjade kan ti Sẹnatọ Ayoade Adeseun, Oloye Sarafa Alli, Amofin Ayo Ojeniyi ati Asofin Tolu Sadipe dijọ fi ọwọ si wa kan saara si awọn ọmọ ẹgbẹ naa fun bi wọn se se ojuse wọn nilana isejọba awa ara wa. Bakan naa ni wọn yonbo wọn fun bi wsn ko se gba ki alaga ipade idibo abẹnu naa dari idibo mọkaruru, eyi to mu mẹrin ninu awọn ọmọ igbimọ alako ipade naa kọwe fipo silẹ. Wayi o, awọn igun ẹgbẹ oselu APC ti inu n bi ti n fi apa janu lori esi idibo abẹnu naa nibi ti Isaac Omodewu ti jawe olubori bii alaga ẹgbẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-59108083
1entertainment
Majek Fashek: Ṣé lóòtọ́ ni Òdú olórin Raggae, Majek Fashek jáde láyé?
Iroyin kan ni ọjọ aiku pe lo gbalẹ kan pe gbajugbaja olorin Raggae ọmọ Naijiria nni, Majek Fashek ti dagbere faye. Ohun ti iroyin naa, eleyii to ti farahan lori ọpọlọpọ awọn oju opo aiyelujara titi kan Wikipedia ṣalaye pe, Majek Fashek mi eemi ikẹyin rẹ ni ọjọ Aiku ni ilu London, ni orilẹede Gẹẹsi. Amọṣa, ohun ti alamojuto ẹgbẹ oṣere rẹ, Uzoma Omenka sọ ninu fidio kan, eyi to fi sita loju opo instagram Majek Fashek ni pe, ko si nnkan to ṣe Majek o. O ni ko ku, ṣugbọn ara rẹ ko le. Fidio naa eyi to fi sita ni nnkan bii agogo mejila oru ọjọ Aje, Uzoma Omenka ni ko yẹ ki ẹnikẹni maa gbadura iku fun agba onkọrin naa. nigba ti BBC Yoruba kan sii, O ni ohun to nile ni owo iranwọ fun itọju rẹ ati pe ọpọ awọn eeyan lo ti n pe lọtun losi lati igba ti iroyin naa ti jade. "Majek ko ku o, ojojo diẹ̀ lo kan n ṣe ogun rẹ" Ti a ba n sọ ninu awọn onkọrin ọmọ orilẹede Naijiria ti gbogbo agbaye mọ bi ẹnii mọ owo, ti orin rẹ si ti gbe ogo ba orilẹede Naijiria ni ọpọlọpọ igba, Majek Fashek jẹ ọkan pataki ninu wọn. Ọdun 1962 ni wọn bi Majek Fashek ni ilu Benin, ni ipinlẹ Edo. Ni aipẹ yii ni iroyin kan kọkọ jade pe arun jẹjẹrẹ mu Majek Fashek ti wọn si n beere iranlọwọ fun un, Iroyin iku rẹ kọkọ ti tan jade ni ọjọ diẹ sẹyin ki alamojuto ẹgbẹ akọrin rẹ, Uzoma Omenka to gbe fidio kan sita pe irọ ni ṣugbọn o fi idi rẹ mulẹ nigba naa pe lootọ ni aisan da agba akọrin naa dubu Amọṣa iroyin naa ṣebi ẹni pe ko dawọ duro. Lara awọn manigbagbe orin ti Majek Fashek gbe jade ni Send down the rain eyi to fun un ni inagijẹ The rainmaker. Awo orin Prisoner of Conscience and I&I Experience(1989),So long too long (1991) Orukọ abisọ rẹ gangan ni Majẹkodunmi Fasheke. Ile iwosan Queen Elizabeth Hospital, Woolwich ni o ti n gba iwosan ni ilu London.lẹ.
Majek Fashek: Ṣé lóòtọ́ ni Òdú olórin Raggae, Majek Fashek jáde láyé? Iroyin kan ni ọjọ aiku pe lo gbalẹ kan pe gbajugbaja olorin Raggae ọmọ Naijiria nni, Majek Fashek ti dagbere faye. Ohun ti iroyin naa, eleyii to ti farahan lori ọpọlọpọ awọn oju opo aiyelujara titi kan Wikipedia ṣalaye pe, Majek Fashek mi eemi ikẹyin rẹ ni ọjọ Aiku ni ilu London, ni orilẹede Gẹẹsi. Amọṣa, ohun ti alamojuto ẹgbẹ oṣere rẹ, Uzoma Omenka sọ ninu fidio kan, eyi to fi sita loju opo instagram Majek Fashek ni pe, ko si nnkan to ṣe Majek o. O ni ko ku, ṣugbọn ara rẹ ko le. Fidio naa eyi to fi sita ni nnkan bii agogo mejila oru ọjọ Aje, Uzoma Omenka ni ko yẹ ki ẹnikẹni maa gbadura iku fun agba onkọrin naa. nigba ti BBC Yoruba kan sii, O ni ohun to nile ni owo iranwọ fun itọju rẹ ati pe ọpọ awọn eeyan lo ti n pe lọtun losi lati igba ti iroyin naa ti jade. "Majek ko ku o, ojojo diẹ̀ lo kan n ṣe ogun rẹ" Ti a ba n sọ ninu awọn onkọrin ọmọ orilẹede Naijiria ti gbogbo agbaye mọ bi ẹnii mọ owo, ti orin rẹ si ti gbe ogo ba orilẹede Naijiria ni ọpọlọpọ igba, Majek Fashek jẹ ọkan pataki ninu wọn. Ọdun 1962 ni wọn bi Majek Fashek ni ilu Benin, ni ipinlẹ Edo. Ni aipẹ yii ni iroyin kan kọkọ jade pe arun jẹjẹrẹ mu Majek Fashek ti wọn si n beere iranlọwọ fun un, Iroyin iku rẹ kọkọ ti tan jade ni ọjọ diẹ sẹyin ki alamojuto ẹgbẹ akọrin rẹ, Uzoma Omenka to gbe fidio kan sita pe irọ ni ṣugbọn o fi idi rẹ mulẹ nigba naa pe lootọ ni aisan da agba akọrin naa dubu Amọṣa iroyin naa ṣebi ẹni pe ko dawọ duro. Lara awọn manigbagbe orin ti Majek Fashek gbe jade ni Send down the rain eyi to fun un ni inagijẹ The rainmaker. Awo orin Prisoner of Conscience and I&I Experience(1989),So long too long (1991) Orukọ abisọ rẹ gangan ni Majẹkodunmi Fasheke. Ile iwosan Queen Elizabeth Hospital, Woolwich ni o ti n gba iwosan ni ilu London.lẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49712097
2health
Masturbation: Ire ni àbí ibi fún ìlera ẹ̀dá?
Awọn eeyan kii ṣaba sọrọ nipa fifun ara ẹni ni adun ibalopọ, paapa ni gbangba. Kii ṣe nilẹ Afirika nikan ni wọn ti ma n fi oju buruku wo o, bakan naa ni ọrọ ri ni awọn apa ibikan nilẹ India ati Asia. Idi ni pe iwa idọti, nnkan ti eeyan ko gbọdọ danwo, ni wọn maa n pe e. Ṣugbọn ṣa, o dabi ẹni pe 'masturbation' ni awọn anfaani kan to n ṣe fun ilera ẹda. Abajade iwadii wa re e: Gẹgẹ bi Cynthia Fogoe, onimọ nipa ibalopọ ṣe sọ, fifun ara ẹni ni adun tabi itẹlọrun ibalopọ, ni iwulo to n ṣe fun ara. O sọ fun akọroyin BBC, Mobeeb Azar, lasiko ifọrọwerọ kan pe, awọn anfaani bayii lo n fun ni: Bakan naa ni Dokita kan ni Naijiria,Chidinma Njoku, sọ pe: Amọ Njoku fikun un pe gbogbo nnkan to n dan kọ ni wura, ninu ọrọ titẹ ara ẹni lọrun fun ibalopọ. Awọn abawọn tabi ewu to wa nibẹ nkọ? Fogoe ṣalaye pe awọn ijamba kan wa ti iwa yii le ṣe fun awọn to ba n ṣe e. Fun awọn ọkunrin to ba ma n se e, o ṣe e ṣe ko bẹrẹ sini nira fun wọn lati pẹ lori ibalopọ pẹlu obinrin. Ti o ba n ṣe e ni gbogbo igba, n ṣe ni o n sọ fun ọpọlọ rẹ pe ọna kan ṣoṣo (masturbation) to wa niyẹn lati ni itura ibalopọ. Eyi tun tumọ si pe, o le nira fun nnkan ọmọkunrin awọn ọkunrin kan lati dide tabi duro fun igba pipẹ lasiko ibalopọ. Fagoe sọ pe, awọn ọkunrin kan ti ẹ le ma damira lẹyin ibalopọ. Ko tan sibẹ o, iwadii ijinlẹ kan tun sọ pe, wiwo fidio ibalopọ - to ṣaba ma n waye pẹlu titẹ ara ẹni lọrun, ma n ni ipa ti ko dara lara ọpọlọ. Wiwo awọn fidio yii tabi fifun ara ẹni ni adun ibalopọ, ma n mu adinku ba bi ibalopọ ṣe ma n wu ọkunrin si pẹlu iyawo tabi ọrẹbinrin wọn. Iyalẹnu to wa nibẹ ni pe, ti ọpọ ba n ronu nipa 'masturbation', ọkunrin ni wọn ma n ro o si. Ṣugbọn, Radhika Sanghani to jẹ akọroyin gba pe eyi ko ri bẹ ẹ. O sọ pe "awọn obinrin ma n ṣe e, amọ wọn kii ṣaba sọrọ nipa rẹ". Bakan naa lo sọ pe awọn obinrin kan ko ti ẹ jẹwọ ri pe awọ́n ma n se e tabi wọn ti ṣe e ri. "Eyi jẹ ibanujẹ fun mi, nitori pe ọpọlọpọ obinrin ti ọjọ ori wọn le ni ogun ọdun, lo ni idalẹbi ati itiju to ma n tẹle ti wọn ba fi le sọ sita. Paapa lati ọdọ ẹbi ati ile ijọsin wọn pẹlu.
Masturbation: Ire ni àbí ibi fún ìlera ẹ̀dá? Awọn eeyan kii ṣaba sọrọ nipa fifun ara ẹni ni adun ibalopọ, paapa ni gbangba. Kii ṣe nilẹ Afirika nikan ni wọn ti ma n fi oju buruku wo o, bakan naa ni ọrọ ri ni awọn apa ibikan nilẹ India ati Asia. Idi ni pe iwa idọti, nnkan ti eeyan ko gbọdọ danwo, ni wọn maa n pe e. Ṣugbọn ṣa, o dabi ẹni pe 'masturbation' ni awọn anfaani kan to n ṣe fun ilera ẹda. Abajade iwadii wa re e: Gẹgẹ bi Cynthia Fogoe, onimọ nipa ibalopọ ṣe sọ, fifun ara ẹni ni adun tabi itẹlọrun ibalopọ, ni iwulo to n ṣe fun ara. O sọ fun akọroyin BBC, Mobeeb Azar, lasiko ifọrọwerọ kan pe, awọn anfaani bayii lo n fun ni: Bakan naa ni Dokita kan ni Naijiria,Chidinma Njoku, sọ pe: Amọ Njoku fikun un pe gbogbo nnkan to n dan kọ ni wura, ninu ọrọ titẹ ara ẹni lọrun fun ibalopọ. Awọn abawọn tabi ewu to wa nibẹ nkọ? Fogoe ṣalaye pe awọn ijamba kan wa ti iwa yii le ṣe fun awọn to ba n ṣe e. Fun awọn ọkunrin to ba ma n se e, o ṣe e ṣe ko bẹrẹ sini nira fun wọn lati pẹ lori ibalopọ pẹlu obinrin. Ti o ba n ṣe e ni gbogbo igba, n ṣe ni o n sọ fun ọpọlọ rẹ pe ọna kan ṣoṣo (masturbation) to wa niyẹn lati ni itura ibalopọ. Eyi tun tumọ si pe, o le nira fun nnkan ọmọkunrin awọn ọkunrin kan lati dide tabi duro fun igba pipẹ lasiko ibalopọ. Fagoe sọ pe, awọn ọkunrin kan ti ẹ le ma damira lẹyin ibalopọ. Ko tan sibẹ o, iwadii ijinlẹ kan tun sọ pe, wiwo fidio ibalopọ - to ṣaba ma n waye pẹlu titẹ ara ẹni lọrun, ma n ni ipa ti ko dara lara ọpọlọ. Wiwo awọn fidio yii tabi fifun ara ẹni ni adun ibalopọ, ma n mu adinku ba bi ibalopọ ṣe ma n wu ọkunrin si pẹlu iyawo tabi ọrẹbinrin wọn. Iyalẹnu to wa nibẹ ni pe, ti ọpọ ba n ronu nipa 'masturbation', ọkunrin ni wọn ma n ro o si. Ṣugbọn, Radhika Sanghani to jẹ akọroyin gba pe eyi ko ri bẹ ẹ. O sọ pe "awọn obinrin ma n ṣe e, amọ wọn kii ṣaba sọrọ nipa rẹ". Bakan naa lo sọ pe awọn obinrin kan ko ti ẹ jẹwọ ri pe awọ́n ma n se e tabi wọn ti ṣe e ri. "Eyi jẹ ibanujẹ fun mi, nitori pe ọpọlọpọ obinrin ti ọjọ ori wọn le ni ogun ọdun, lo ni idalẹbi ati itiju to ma n tẹle ti wọn ba fi le sọ sita. Paapa lati ọdọ ẹbi ati ile ijọsin wọn pẹlu.
https://www.bbc.com/yoruba/agbaye-54044241
4religion
'A ti ní òye gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi ìkọlù ìjọ Kátólíìkì Owo, àmọ́ ...'
"Ẹ ò kàn lè máa ṣa èèyàn káàkiri lónìí, lọ́la pé àwọn ló ṣe ìkọlù yìí". Alukoro Ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti ba BBC Yoruba sọrọ lori igbesẹ ti wọn n gbe lori ikọlu to waye ni ijọ Katoliiki ilu Owo. Ọgbẹni Olumuyiwa Adejobi ni nkan buruku ni nkan to ṣẹlẹ yii gbogbo awọn si lawọn kọ ọ tori iwa ẹranko ti ko daa ni lawujọ. "Bí ajá bá pé ogún ọdún láyé, ẹran ogun ni o! Gbogbo awọn to ṣe iṣẹ yii ni Owo, wọn o ni lọ". Bakan naa lo fesi si awọn eeyan ti wọn n sọ pe wọn joko tẹtẹrẹ lori ọrọ naa pe awọn ti ni oye gbogbo nkan to ṣẹlẹ, amọ wọn gbudọ ṣe iwadii kikun. "Kii ṣe pe ka maa ṣa eeyan kiri lọtun losi, a gbudọ rii daju pe awọn to ṣe iṣẹ ibi yii gangan la mu".
'A ti ní òye gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi ìkọlù ìjọ Kátólíìkì Owo, àmọ́ ...' "Ẹ ò kàn lè máa ṣa èèyàn káàkiri lónìí, lọ́la pé àwọn ló ṣe ìkọlù yìí". Alukoro Ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti ba BBC Yoruba sọrọ lori igbesẹ ti wọn n gbe lori ikọlu to waye ni ijọ Katoliiki ilu Owo. Ọgbẹni Olumuyiwa Adejobi ni nkan buruku ni nkan to ṣẹlẹ yii gbogbo awọn si lawọn kọ ọ tori iwa ẹranko ti ko daa ni lawujọ. "Bí ajá bá pé ogún ọdún láyé, ẹran ogun ni o! Gbogbo awọn to ṣe iṣẹ yii ni Owo, wọn o ni lọ". Bakan naa lo fesi si awọn eeyan ti wọn n sọ pe wọn joko tẹtẹrẹ lori ọrọ naa pe awọn ti ni oye gbogbo nkan to ṣẹlẹ, amọ wọn gbudọ ṣe iwadii kikun. "Kii ṣe pe ka maa ṣa eeyan kiri lọtun losi, a gbudọ rii daju pe awọn to ṣe iṣẹ ibi yii gangan la mu".
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cw53pxd1l0ko
1entertainment
Ada Jesus death: Ṣé òtítọ́ ni pé ikú apanilẹ́ẹ̀rín Ada Jesus lọ́wọ́ ayé nínú?
Harrison Gwamnishu to jẹ olutọju adẹrinpoṣonu to jade laye, Mmesoma Mercy Obi ti awọn eeyan mọ si Ada ti kede pe iku to pa a ko lọwọ aye ninu. O ṣalaye wi pe aisan to ti n ṣe e fun ọjọ pipẹ lo gba ẹmi apanilẹrin naa. Gwamnishu sọrọ yii laarọ Ọjọbọ lẹyin ti iku Ada Jesus ya awọn eeyan lẹnu ni Ọjọru. Ki o to di wi pe olutọju Ada Jesus ba a pade, ailera rẹ ti wọ ọ lara gan an debi pe ko le da sọrọ daadaa mọ. Gwamnishu sọ fun BBC pe iku ati ọdọ Ọlọrun lo pa Ada Jesus. ''Iru iku to pa Ada Jesus to fi ọmọ saye lọ jẹ iru iku to maa ṣaaba pa ọpọ eeyan. Ada ko ba ti ku to jẹ wi pe wọn tete gbe lọ si ile iwosan ni ṣugbọn aisan naa ti wọ ọ lara pupọ, wọn dokita gan an fidi rẹ mulẹ bẹẹ. Ara rẹ ti n balẹ diẹ diẹ nigba ti wọn gbe e wa si ibudo itọju awọn to larun kindinrin. Koda, ọpọ eeyan eeyan lo ti dawo iranwọ fun itọju Ada Jesus ṣugbọn o ṣeni laanu pe o pada ku,'' Gwamnishu ṣalaye. Gwamnishu sọ pe oun atawọn eeyan kan ti bẹrẹ si ni ba ile iwosan Fortis sọrọ niluu Mumbai lorilẹede India lori ati gbe Ada Jesus lọ fun itọju arun kindinrin. O ni awọn fẹ ki o gbadun diẹ ki awọn to gbe e lọ si India lati ṣiṣẹ abẹ ipaarọ kindinrin rẹ ki ẹlẹmi to pada gba a. Gwamnishu fikun ọrọ rẹ pe awọn eeyan kan tiẹ n bẹbẹ lati da owo iranwọ fun itọju Ada Jesus, ṣugbọn gbogbo rẹ ti tan bayii. Olutọju Ada Jesus sọ pe lootọọ ni adẹrinpoṣonu naa ti ku, ṣugbọn awọn ẹbi rẹ si nilo iranlọwọ awọn eeyan. Gwamnishu ni ''Ada Jesus fi ọmọ silẹ saye lọ, ọmọ naa si nilo iranwọlọwọ awọn eeyan. O tun tan imọlẹ si ọrọ kan tawọn eeyan kan n sọ pe ko beere iranwọ owo fun itọju Ada lori ẹrọ ayelujara. Gwamnishu ni owo kọ ni iṣoro lori ailera Ada Jesus nitori Onimọ ẹrọ Marksman Chinedu Ijiomah ṣetan lati fi miliọnu mẹwaa silẹ fun itọju rẹ.
Ada Jesus death: Ṣé òtítọ́ ni pé ikú apanilẹ́ẹ̀rín Ada Jesus lọ́wọ́ ayé nínú? Harrison Gwamnishu to jẹ olutọju adẹrinpoṣonu to jade laye, Mmesoma Mercy Obi ti awọn eeyan mọ si Ada ti kede pe iku to pa a ko lọwọ aye ninu. O ṣalaye wi pe aisan to ti n ṣe e fun ọjọ pipẹ lo gba ẹmi apanilẹrin naa. Gwamnishu sọrọ yii laarọ Ọjọbọ lẹyin ti iku Ada Jesus ya awọn eeyan lẹnu ni Ọjọru. Ki o to di wi pe olutọju Ada Jesus ba a pade, ailera rẹ ti wọ ọ lara gan an debi pe ko le da sọrọ daadaa mọ. Gwamnishu sọ fun BBC pe iku ati ọdọ Ọlọrun lo pa Ada Jesus. ''Iru iku to pa Ada Jesus to fi ọmọ saye lọ jẹ iru iku to maa ṣaaba pa ọpọ eeyan. Ada ko ba ti ku to jẹ wi pe wọn tete gbe lọ si ile iwosan ni ṣugbọn aisan naa ti wọ ọ lara pupọ, wọn dokita gan an fidi rẹ mulẹ bẹẹ. Ara rẹ ti n balẹ diẹ diẹ nigba ti wọn gbe e wa si ibudo itọju awọn to larun kindinrin. Koda, ọpọ eeyan eeyan lo ti dawo iranwọ fun itọju Ada Jesus ṣugbọn o ṣeni laanu pe o pada ku,'' Gwamnishu ṣalaye. Gwamnishu sọ pe oun atawọn eeyan kan ti bẹrẹ si ni ba ile iwosan Fortis sọrọ niluu Mumbai lorilẹede India lori ati gbe Ada Jesus lọ fun itọju arun kindinrin. O ni awọn fẹ ki o gbadun diẹ ki awọn to gbe e lọ si India lati ṣiṣẹ abẹ ipaarọ kindinrin rẹ ki ẹlẹmi to pada gba a. Gwamnishu fikun ọrọ rẹ pe awọn eeyan kan tiẹ n bẹbẹ lati da owo iranwọ fun itọju Ada Jesus, ṣugbọn gbogbo rẹ ti tan bayii. Olutọju Ada Jesus sọ pe lootọọ ni adẹrinpoṣonu naa ti ku, ṣugbọn awọn ẹbi rẹ si nilo iranlọwọ awọn eeyan. Gwamnishu ni ''Ada Jesus fi ọmọ silẹ saye lọ, ọmọ naa si nilo iranwọlọwọ awọn eeyan. O tun tan imọlẹ si ọrọ kan tawọn eeyan kan n sọ pe ko beere iranwọ owo fun itọju Ada lori ẹrọ ayelujara. Gwamnishu ni owo kọ ni iṣoro lori ailera Ada Jesus nitori Onimọ ẹrọ Marksman Chinedu Ijiomah ṣetan lati fi miliọnu mẹwaa silẹ fun itọju rẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-56842315
1entertainment
Adio Atawẹwẹ: Orin Fuji ló gba iwé kíkà lọ́wọ́ mi
Gbajugbaju olorin Fuji, Alhaji Sulaimọn Adio Atawẹwẹ sọ pe lati igba t'oun ti gbọ́nju, oloogbe Dr Sikiru Ayinde Barrister ni akọkọ olorin Fuji. Atawẹwẹ fọrọ yii lede ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba nile rẹ niluu Ikorodu l'Ọjọru. Alhaji Adio ni, lati kekere loun ti n gbọ awo orin ti Barrister ti kọ wéré, ko to maa kọ orin Fuji. Amọ, o ni ti ẹnikan ba sọ pe Barrister kọ lo da Fuji silẹ, o ni ko si ija nibẹ nitori ohun to kọju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomiran. Atawẹwẹ tun fikun ọrọ rẹ pe, iṣẹ Fuji lo yọ oun ninu iṣẹ alabaru lọja Ketu ati Mile 12. O ni oun tun ṣiṣẹ apero sọkọ ati iṣẹ akọle, birikila ṣugbọn iṣẹ Fuji lo yọ ọpọ eeyan to n kọ Fuji loko ẹru. O tun salaye pe, apọnle ti wọn ba n fun Fela lo yẹ ki wọn maa fun Barrister kaakiri gbogbo agbaye. Atawẹwẹ fikun ọrọ rẹ pe, o yẹ ki gbogbo olorin Fuji mọ ere Ayinde Barrister ati ti Alhaji Ayinla Kollington, lati fi gboṣuba fun wọn. O ni awọn mejeeji ni wọn yọ ọpọ olorin Fuji loko ẹru lonii. Atawẹwẹ sọ pe, ati ọmọ ọdun mẹrin ni oun ti n kọrin, orin kikọ si lo gbawe kika lọwọ oun. O ni JSS 3 loun wa nile iwe girama ki oun to kuro nile iwe, amọ o sọ pe oun o kaba
Adio Atawẹwẹ: Orin Fuji ló gba iwé kíkà lọ́wọ́ mi Gbajugbaju olorin Fuji, Alhaji Sulaimọn Adio Atawẹwẹ sọ pe lati igba t'oun ti gbọ́nju, oloogbe Dr Sikiru Ayinde Barrister ni akọkọ olorin Fuji. Atawẹwẹ fọrọ yii lede ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba nile rẹ niluu Ikorodu l'Ọjọru. Alhaji Adio ni, lati kekere loun ti n gbọ awo orin ti Barrister ti kọ wéré, ko to maa kọ orin Fuji. Amọ, o ni ti ẹnikan ba sọ pe Barrister kọ lo da Fuji silẹ, o ni ko si ija nibẹ nitori ohun to kọju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomiran. Atawẹwẹ tun fikun ọrọ rẹ pe, iṣẹ Fuji lo yọ oun ninu iṣẹ alabaru lọja Ketu ati Mile 12. O ni oun tun ṣiṣẹ apero sọkọ ati iṣẹ akọle, birikila ṣugbọn iṣẹ Fuji lo yọ ọpọ eeyan to n kọ Fuji loko ẹru. O tun salaye pe, apọnle ti wọn ba n fun Fela lo yẹ ki wọn maa fun Barrister kaakiri gbogbo agbaye. Atawẹwẹ fikun ọrọ rẹ pe, o yẹ ki gbogbo olorin Fuji mọ ere Ayinde Barrister ati ti Alhaji Ayinla Kollington, lati fi gboṣuba fun wọn. O ni awọn mejeeji ni wọn yọ ọpọ olorin Fuji loko ẹru lonii. Atawẹwẹ sọ pe, ati ọmọ ọdun mẹrin ni oun ti n kọrin, orin kikọ si lo gbawe kika lọwọ oun. O ni JSS 3 loun wa nile iwe girama ki oun to kuro nile iwe, amọ o sọ pe oun o kaba
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49100660
3politics
Atiku àti Davido sọ̀rọ̀ sókè nípa bí ìjọba Buhari ṣé ti àkáúntì ''cryptocurrency'' pa
Eti yin to gbọ alọ nipa ikede ijọba apapọ Naijria lati ti akaunti awọn to n ṣe karakata owo Crptocurrency yẹ ki o gbọ abọ. Idi ree ti a fi ni ka mu tọ yin wa ohun tawọn ọmọ Naijriria ti n sọ nipa ikede yi. Tolori tẹlẹmu lo ti n da si ọrọ. Ninu awọn to gbaujumọ taa le tọka si ni igbakeji aarẹ ana, Atiku Abubakar. Atiku to jẹ gbajugbaja onisowo to si ni ọpọ ileeṣẹ sọ pe nkan ti Naijria nilo lasiko yi ni pipese iṣẹ lati le jẹ ki ọrọ aje burẹkẹ si. Asiko yi kọ lo yẹ ki ijọba fofin de karakata ti yoo maa jẹ ki owo wọle si ẹka ọrọ aje wa ni ohun ti Atiku sọ. O ṣalaye pe ''o ṣeeṣe ki ijọba mojuto cryptocurrency yi ati bi owo ti se n wọle si Naijiria lai se akoba fun aabo orileede wa.Eyi ṣuwọn ju ki wọn ti i pa lọ'' O tẹsiwaju pe ''awọn ọdọ Naijiria n koju inira airiṣe nitori naa o y ki ijọba pese iṣẹ lati le jẹ ki ẹka ọrọ aje gbooro si'' Ẹwẹ awọn ọmọ Naijiria mii ti n da si ọrọ yi. Ninu wọn ni arakunrin Osasu Obayiuwana to sọ pe aini igbagbọ ninu eto ọrọ aje banki apapọ Naijiri lo mu kawọn eeyan ya sidi Cryptocurrency. Gbajugbaja olorin takasufe Naijiria Davido naa da si ọrọ yi. Loju opo rẹ ni Twitter, OBO ni oun ṣẹṣẹ n gbero lati darapọ mọ owo crypto ni ki ikede ijọba apapọ yi to jade. Ọrọ yi gẹgẹ bi o ṣe sọ fun awọn eeyan miliọnu mẹjọ to n tẹle loju opo rẹ jẹ iyalẹnu Awọn mii to tun sọrọ ati ohun ti wọn wi ree: Gbogbo ẹyin to n ṣe kata kara owo ''cryptocurrency'' ni Naijiria, ẹ jawọ nbẹ tori o lodi sofin orilẹede yii. Banki apapọ ni Naijiria CBN ti paṣẹ fun gbogbo ile ifowopamọ lorilẹede Najiria lati gbe apo ikowosi awọn eeyan to ba n ṣe kata kara owo 'cryptocurrency'' ti pa. Koda CBN paṣẹ fawṣon ile ifowopamọ lati ṣe awari gbogbo awọn onibara wọn to ni apo ikowosi fun owo ''crypo'' ki wọn si ti wọn pa lẹsẹ kẹsẹ. CBN ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita ti ọga ẹka to n ṣe amojuto ni banki naa, Bello Hassan buwọlu pe kilọ fawọn ile ifowopamọ ni Naijiria ewu to wa ninu kiko owo ''crypo'' si banki wọn. Banki CBN sọ ninu atẹjade ọhun pe ile ifowopamọ kankan ko gbọdọ ni ohun kohun ṣe pẹlu kata kara mọ bayii. Banki CBN sọ ninu atẹjade ọhun pe ẹnikẹni to ba tapa si ikede yii yoo foju win ofin. Ẹwẹ, ọgọọrọ ọmọ Naijiria lo ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ banki apapọ Najiria. Awọn ilumọọka lori ayelujara bii Shehu Sani, Reno Omokri, Ben Murray-Bruce, Omoyele Sowore, Debo Macaroni, DJ Switch ati awọn mii lo koro oju si igbesẹ ijọba.
Atiku àti Davido sọ̀rọ̀ sókè nípa bí ìjọba Buhari ṣé ti àkáúntì ''cryptocurrency'' pa Eti yin to gbọ alọ nipa ikede ijọba apapọ Naijria lati ti akaunti awọn to n ṣe karakata owo Crptocurrency yẹ ki o gbọ abọ. Idi ree ti a fi ni ka mu tọ yin wa ohun tawọn ọmọ Naijriria ti n sọ nipa ikede yi. Tolori tẹlẹmu lo ti n da si ọrọ. Ninu awọn to gbaujumọ taa le tọka si ni igbakeji aarẹ ana, Atiku Abubakar. Atiku to jẹ gbajugbaja onisowo to si ni ọpọ ileeṣẹ sọ pe nkan ti Naijria nilo lasiko yi ni pipese iṣẹ lati le jẹ ki ọrọ aje burẹkẹ si. Asiko yi kọ lo yẹ ki ijọba fofin de karakata ti yoo maa jẹ ki owo wọle si ẹka ọrọ aje wa ni ohun ti Atiku sọ. O ṣalaye pe ''o ṣeeṣe ki ijọba mojuto cryptocurrency yi ati bi owo ti se n wọle si Naijiria lai se akoba fun aabo orileede wa.Eyi ṣuwọn ju ki wọn ti i pa lọ'' O tẹsiwaju pe ''awọn ọdọ Naijiria n koju inira airiṣe nitori naa o y ki ijọba pese iṣẹ lati le jẹ ki ẹka ọrọ aje gbooro si'' Ẹwẹ awọn ọmọ Naijiria mii ti n da si ọrọ yi. Ninu wọn ni arakunrin Osasu Obayiuwana to sọ pe aini igbagbọ ninu eto ọrọ aje banki apapọ Naijiri lo mu kawọn eeyan ya sidi Cryptocurrency. Gbajugbaja olorin takasufe Naijiria Davido naa da si ọrọ yi. Loju opo rẹ ni Twitter, OBO ni oun ṣẹṣẹ n gbero lati darapọ mọ owo crypto ni ki ikede ijọba apapọ yi to jade. Ọrọ yi gẹgẹ bi o ṣe sọ fun awọn eeyan miliọnu mẹjọ to n tẹle loju opo rẹ jẹ iyalẹnu Awọn mii to tun sọrọ ati ohun ti wọn wi ree: Gbogbo ẹyin to n ṣe kata kara owo ''cryptocurrency'' ni Naijiria, ẹ jawọ nbẹ tori o lodi sofin orilẹede yii. Banki apapọ ni Naijiria CBN ti paṣẹ fun gbogbo ile ifowopamọ lorilẹede Najiria lati gbe apo ikowosi awọn eeyan to ba n ṣe kata kara owo 'cryptocurrency'' ti pa. Koda CBN paṣẹ fawṣon ile ifowopamọ lati ṣe awari gbogbo awọn onibara wọn to ni apo ikowosi fun owo ''crypo'' ki wọn si ti wọn pa lẹsẹ kẹsẹ. CBN ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita ti ọga ẹka to n ṣe amojuto ni banki naa, Bello Hassan buwọlu pe kilọ fawọn ile ifowopamọ ni Naijiria ewu to wa ninu kiko owo ''crypo'' si banki wọn. Banki CBN sọ ninu atẹjade ọhun pe ile ifowopamọ kankan ko gbọdọ ni ohun kohun ṣe pẹlu kata kara mọ bayii. Banki CBN sọ ninu atẹjade ọhun pe ẹnikẹni to ba tapa si ikede yii yoo foju win ofin. Ẹwẹ, ọgọọrọ ọmọ Naijiria lo ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ banki apapọ Najiria. Awọn ilumọọka lori ayelujara bii Shehu Sani, Reno Omokri, Ben Murray-Bruce, Omoyele Sowore, Debo Macaroni, DJ Switch ati awọn mii lo koro oju si igbesẹ ijọba.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-55951663
3politics
Wọ́n lù mí, kódà wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn ní Alaba- Lawal Waheed
A tun ti gbe ise wa de lori ikanni yi nipa titan imọlẹ si iroyin to ba ruju lawujọ wa ni Naijiria tabi nibomiran. Lọtẹ yi, ohun taa fẹ gbe yẹwo ni iroyin to gbode pe awọn kan n kọdi awọn ẹya Igbo lati le forukọsilẹ gba kaadi idibo PVC ni ọja Alaba ni ipinlẹ Eko. Ninu fọnran fidio kan ni ọrọ yi ti ṣebi ẹni jade. Kini nkan taa mọ nipa rẹ? Ṣe lootọ ni abi iroyin ofege leleyi naa? Alaye ree: Ninu fidio yi nkan taa ri ni pe awọn eeyan kan n sọ ni ileeṣẹ́ INEC to wa ni Igbede ijọba ibilẹ Ọjọọ ni Eko pe wọn ko jẹ ki awọn forukọsilẹ gba kaadi idibo PVC notori pe awọn jẹ ẹya Igbo. Ẹya Igbo yi jẹ ọkan lara awọn ẹya orileede Naijiria to wa ni iha Guusu ilẹ naa. Ni ọja ilumọọka nii, ọja Alaba ni iṣẹlẹ yi si ti waye. Awọn oniṣowo ẹya Igbo pọ ni ọja yi daadaa. Loju opo Twitter ni paapa lawọn eeyan ti n ṣe alabapin fidio lori ọrọ yi ti onikaluku si n sọ ohun to ro nipa iṣẹlẹ naa. A gbọ ninu fidio kan tawọn eeyan to n kọja si n sọrọ lede Igbo pe ''se awọn eeyan to n ja ninu ọfisi INEC lagbara lati ja ni? Ṣugbọn o ṣoju mi koro sọ fun BBC pe wahala to waye ko niṣe pẹlu pe oṣiṣẹ INEC ko jẹ ki awọn eeyan forukọsilẹ nitori ẹya wọn. Ọkan lara awọn taa ba sọrọ, Chinaza Ikemeziem, sọ pe nkan to da ija silẹ nipe awọn eeyan kan yari pe ki awọn oṣiṣẹ INEC ma gbe irinṣẹ iforukọ́silẹ wọn kuro ninu ọfisi naa. ''Ohun to ṣẹlẹ ko ṣẹyin pe awọn ero pọ. Wọn ti ọja Alaba tori ki awọn eeyan baa le jade wa gba kaadi idibo. Ẹgbẹgbẹrun lawọn to tu sita ti ipa awọn oṣiṣẹ INEC ko si kawọn. Ohun to fa wahala nibi oṣiṣẹ INEC kan se wa lati gbe irinṣẹ iforukọsilẹ lọ si ibomiran ti wọn ti n ṣe iforukọsilẹ. Awọn to wa nibẹ yari fun wọn ibẹ si ni wahala ti bẹrẹ'' Arabinrin Ikemesiem lo ṣalaye ọrọ yi fun BBC. O ni ṣaaju ki wahala naa to waye, ko si ede aiyede kankan to niiṣe pẹlu ọrọ ẹlẹyamẹya. ''Ẹrọ iforukọsilẹ kan ṣoṣo lo wa nibẹ awọn to si wa forukọsilẹ ko fẹ ki wọn gbe lọ ni nkan to ṣẹlẹ'' Arakunrin Lawal Waheed, ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ fun BBC pe awọn eeyan doju ija kọ oun nigba toun fẹ daabo bo oṣiṣẹ INEC taa n wi yi. ''O ni awọn irinṣẹ kan ti awọn oṣiṣẹ INEC maa n gbe lọ si awọn adugbo miran kawọn ti ko ba raaye lati wa si ọfiisi wọn naa baa le ribi forukọsilẹ'' O ni iru nkan bayii ko ṣẹṣẹ maa waye nibi tawọn to ba wa forukọsilẹ yoo yari pe wọn ko gbọdọ gbe awọn irinṣẹ yi lọ ayafi bi wọn ba forukọ ti wọn silẹ ṣaaju. ''Gbogbo alaye ti wọn ba n ṣe fun wọn pe ibomiran lawọn ti fẹ lọ lo awọn irinṣẹ yi kii wọ awọn eeyan yi leti. Wọn kọlu oṣiṣẹ INEC ọkunrin kan ṣugbọn ẹni keji rẹ to jẹ obinrin ribi gbe ọkada sa mọ wọn lọwọ'' O ni koda wọn lu oun ti wọn si ya aṣọ mọ oun lọrun nigba toun fẹ gba oṣiṣẹ Inec yi lọwọ wọn. ''Wọn tun lu baalẹ kan lagbege naa eleyi to mu ki awọn ọdọ adugbo ọhun naa wa das i ọrọ to fi di gbas gbos laarin wọn. Arakunrin Waheed ni awọn eeyan kan n sọ pe bawo ni ẹrọ iforukọsilẹ yoo ṣe wa nibi ti wọn ko si ni jẹ ki awọn ẹya Igbo forukọsilẹ. Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye o ni ko si ohun to jọ bẹ to waye nitori ẹya tabi idi miran ju eleyi toun tio ṣalaye lọ. Ẹwẹ aarẹ awọn oniṣowo to n ta ẹrọ ilo ile ni ọja naa Paulinus Ugochuwu ti paṣẹ pe ki wọn ti ọja naa lọjọ kan si ki awọn ọlọja baa le ribi gba kaadi idibo wọn. Bakan naa ni ajọ eleto idibo lorileede Naijiria INEC ti sọ pe awọn mọ inira taraalu n koju ni paapa lori gbigba kaadi idibo ọlọjọ pipe. Ọga INEC to n risi idanilekọ araalu,Festus Okoye lawọn ti fi ẹrọ iforukọsile mii sita lawọn ipinlẹ maraarun to wa ni ila oorun Guusu Naijiria ,Eko ati Kano nibi ti ero ti pọ. Iye ẹrọ to lawọn ko si ta si jẹ mọkandinlaadọfa. O tẹsiwaju pe awọn yoo sayewo bi nkan ba se n lọ lati mọ igbese to kan.
Wọ́n lù mí, kódà wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn ní Alaba- Lawal Waheed A tun ti gbe ise wa de lori ikanni yi nipa titan imọlẹ si iroyin to ba ruju lawujọ wa ni Naijiria tabi nibomiran. Lọtẹ yi, ohun taa fẹ gbe yẹwo ni iroyin to gbode pe awọn kan n kọdi awọn ẹya Igbo lati le forukọsilẹ gba kaadi idibo PVC ni ọja Alaba ni ipinlẹ Eko. Ninu fọnran fidio kan ni ọrọ yi ti ṣebi ẹni jade. Kini nkan taa mọ nipa rẹ? Ṣe lootọ ni abi iroyin ofege leleyi naa? Alaye ree: Ninu fidio yi nkan taa ri ni pe awọn eeyan kan n sọ ni ileeṣẹ́ INEC to wa ni Igbede ijọba ibilẹ Ọjọọ ni Eko pe wọn ko jẹ ki awọn forukọsilẹ gba kaadi idibo PVC notori pe awọn jẹ ẹya Igbo. Ẹya Igbo yi jẹ ọkan lara awọn ẹya orileede Naijiria to wa ni iha Guusu ilẹ naa. Ni ọja ilumọọka nii, ọja Alaba ni iṣẹlẹ yi si ti waye. Awọn oniṣowo ẹya Igbo pọ ni ọja yi daadaa. Loju opo Twitter ni paapa lawọn eeyan ti n ṣe alabapin fidio lori ọrọ yi ti onikaluku si n sọ ohun to ro nipa iṣẹlẹ naa. A gbọ ninu fidio kan tawọn eeyan to n kọja si n sọrọ lede Igbo pe ''se awọn eeyan to n ja ninu ọfisi INEC lagbara lati ja ni? Ṣugbọn o ṣoju mi koro sọ fun BBC pe wahala to waye ko niṣe pẹlu pe oṣiṣẹ INEC ko jẹ ki awọn eeyan forukọsilẹ nitori ẹya wọn. Ọkan lara awọn taa ba sọrọ, Chinaza Ikemeziem, sọ pe nkan to da ija silẹ nipe awọn eeyan kan yari pe ki awọn oṣiṣẹ INEC ma gbe irinṣẹ iforukọ́silẹ wọn kuro ninu ọfisi naa. ''Ohun to ṣẹlẹ ko ṣẹyin pe awọn ero pọ. Wọn ti ọja Alaba tori ki awọn eeyan baa le jade wa gba kaadi idibo. Ẹgbẹgbẹrun lawọn to tu sita ti ipa awọn oṣiṣẹ INEC ko si kawọn. Ohun to fa wahala nibi oṣiṣẹ INEC kan se wa lati gbe irinṣẹ iforukọsilẹ lọ si ibomiran ti wọn ti n ṣe iforukọsilẹ. Awọn to wa nibẹ yari fun wọn ibẹ si ni wahala ti bẹrẹ'' Arabinrin Ikemesiem lo ṣalaye ọrọ yi fun BBC. O ni ṣaaju ki wahala naa to waye, ko si ede aiyede kankan to niiṣe pẹlu ọrọ ẹlẹyamẹya. ''Ẹrọ iforukọsilẹ kan ṣoṣo lo wa nibẹ awọn to si wa forukọsilẹ ko fẹ ki wọn gbe lọ ni nkan to ṣẹlẹ'' Arakunrin Lawal Waheed, ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ fun BBC pe awọn eeyan doju ija kọ oun nigba toun fẹ daabo bo oṣiṣẹ INEC taa n wi yi. ''O ni awọn irinṣẹ kan ti awọn oṣiṣẹ INEC maa n gbe lọ si awọn adugbo miran kawọn ti ko ba raaye lati wa si ọfiisi wọn naa baa le ribi forukọsilẹ'' O ni iru nkan bayii ko ṣẹṣẹ maa waye nibi tawọn to ba wa forukọsilẹ yoo yari pe wọn ko gbọdọ gbe awọn irinṣẹ yi lọ ayafi bi wọn ba forukọ ti wọn silẹ ṣaaju. ''Gbogbo alaye ti wọn ba n ṣe fun wọn pe ibomiran lawọn ti fẹ lọ lo awọn irinṣẹ yi kii wọ awọn eeyan yi leti. Wọn kọlu oṣiṣẹ INEC ọkunrin kan ṣugbọn ẹni keji rẹ to jẹ obinrin ribi gbe ọkada sa mọ wọn lọwọ'' O ni koda wọn lu oun ti wọn si ya aṣọ mọ oun lọrun nigba toun fẹ gba oṣiṣẹ Inec yi lọwọ wọn. ''Wọn tun lu baalẹ kan lagbege naa eleyi to mu ki awọn ọdọ adugbo ọhun naa wa das i ọrọ to fi di gbas gbos laarin wọn. Arakunrin Waheed ni awọn eeyan kan n sọ pe bawo ni ẹrọ iforukọsilẹ yoo ṣe wa nibi ti wọn ko si ni jẹ ki awọn ẹya Igbo forukọsilẹ. Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye o ni ko si ohun to jọ bẹ to waye nitori ẹya tabi idi miran ju eleyi toun tio ṣalaye lọ. Ẹwẹ aarẹ awọn oniṣowo to n ta ẹrọ ilo ile ni ọja naa Paulinus Ugochuwu ti paṣẹ pe ki wọn ti ọja naa lọjọ kan si ki awọn ọlọja baa le ribi gba kaadi idibo wọn. Bakan naa ni ajọ eleto idibo lorileede Naijiria INEC ti sọ pe awọn mọ inira taraalu n koju ni paapa lori gbigba kaadi idibo ọlọjọ pipe. Ọga INEC to n risi idanilekọ araalu,Festus Okoye lawọn ti fi ẹrọ iforukọsile mii sita lawọn ipinlẹ maraarun to wa ni ila oorun Guusu Naijiria ,Eko ati Kano nibi ti ero ti pọ. Iye ẹrọ to lawọn ko si ta si jẹ mọkandinlaadọfa. O tẹsiwaju pe awọn yoo sayewo bi nkan ba se n lọ lati mọ igbese to kan.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cv2pl5lkwq0o
3politics
PDP crisis: Yánpọnyánrin PDP ń fẹjú síi, Uche Secondus ní òun kò bẹ̀rù àṣẹ ilé ẹjọ́, kí ẹgbẹ́ má bàjẹ́ ni tòun
Yanponyanrin laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ti n waye baye fun osẹ diẹ eleyii ti awọn alagbara kan ninu ẹgbẹ naa n pe fun Uche Secondus, alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu naa. Lẹyin ti ile ẹjọ giga kan nipinlẹ Rivers ti ni ko yẹba naa ko si ye e pe ara rẹ ni alaga apapọ ẹgbẹ Oṣelu PDP lorilẹede Naijiria. Ọmọọba Uche Secondus ti ṣalaye pe ko si ohun kan to babara ninu rẹ ju wi pe ki oun pẹlu lọ si ile ẹjọ lati lọ da ile ẹjọ loun ipe rẹ. Onidajọ Okogbule Gbasam ti ileẹjọ giga ipinlẹ Rivers to wa ni Degema ni Portharcourt paṣẹ ni ọjọ Aje petiti di igba ti wọn yoo fi yanju ẹjọ naa o, Secondus ko gbọdọ oe ara rẹ tabi ṣe ojuṣe alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP. Ninu ọrọ ti amugbalẹgbẹ fun Ọmọọba Secondus sọ, alaga ẹgbẹ oṣelu PDP naa ni ẹruko ba oun boti wulẹ ko mọ lori ipẹjọ naa oun si setan lati yọju si ile ẹjọ lori rẹ. "Bi ẹnikẹni ba gbe Secondus ati ẹgbẹ oṣelu PDP lọ sile ẹjọ, o di dandan, yoo farahan ni lati wi tẹnu rẹ. Awọn ọmọ Naijiria lo ni ẹgbẹ oṣelu yiio si tobi ju ẹnikẹni tabi ẹgbẹ kankan lọ titi kan awọn afipa du ipo". Yanponyanrin laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ti n waye baye fun osẹ diẹ eleyii ti awọn kan ninu ẹgbẹ naa ti gomina Nyesom Wike tipinlẹ Rivers ko sodi lati tun igbimọ isakoso ẹgbẹ naa ka. Iléẹjọ́ ní kí alága gbogboogbò PDP, Uche Secondus lọ rọọ́kùn nílé Rogbodiyan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ti fori sọ ibi kan kan lójọ Aje, lẹyin ti ileẹjọ giga ipinlẹ Rivers ni ki ni alaga gbogbo ẹgbẹ naa, Uche Secondus lọ rọkun nile na. Eeyan mẹrin, Ibeabuchi Ernest Alex, Dennis Nna Amadi, Emmanuel Stephen ati Umezirike Onucha lo ni ki ileẹjọ da Secondus duro gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ ọhun. Adajọ ileẹjọ giga ẹkun Degema, O. Gbasam sọ ninu idajọ rẹ pe aṣẹ gun ẹbẹ awọn mẹrin yii. Nkan ko fara rọ ninu ẹgbẹ PDP lori awuyewuye ati yọ Secondus nipo ṣaaju ipade gbogbogbo ẹgbẹ naa to n bọ lọna. Ẹwẹ, Secondus ti sọrọ lẹyin aṣẹ ile ẹjọ to ni ko gbọdọ pe ara rẹ ni alaga PDP mọ. Oludamọran Secondus lori ọrọ iroyin, Ike Abonyi sọ pe Secondus ṣetan lati sọ ti ẹnu rẹ ni ileẹjọ. O ni ẹgbẹ oṣelu PDP kii ṣe dukia ẹnikan, awọn ọmọ Naijiria lo ni i.
PDP crisis: Yánpọnyánrin PDP ń fẹjú síi, Uche Secondus ní òun kò bẹ̀rù àṣẹ ilé ẹjọ́, kí ẹgbẹ́ má bàjẹ́ ni tòun Yanponyanrin laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ti n waye baye fun osẹ diẹ eleyii ti awọn alagbara kan ninu ẹgbẹ naa n pe fun Uche Secondus, alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu naa. Lẹyin ti ile ẹjọ giga kan nipinlẹ Rivers ti ni ko yẹba naa ko si ye e pe ara rẹ ni alaga apapọ ẹgbẹ Oṣelu PDP lorilẹede Naijiria. Ọmọọba Uche Secondus ti ṣalaye pe ko si ohun kan to babara ninu rẹ ju wi pe ki oun pẹlu lọ si ile ẹjọ lati lọ da ile ẹjọ loun ipe rẹ. Onidajọ Okogbule Gbasam ti ileẹjọ giga ipinlẹ Rivers to wa ni Degema ni Portharcourt paṣẹ ni ọjọ Aje petiti di igba ti wọn yoo fi yanju ẹjọ naa o, Secondus ko gbọdọ oe ara rẹ tabi ṣe ojuṣe alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP. Ninu ọrọ ti amugbalẹgbẹ fun Ọmọọba Secondus sọ, alaga ẹgbẹ oṣelu PDP naa ni ẹruko ba oun boti wulẹ ko mọ lori ipẹjọ naa oun si setan lati yọju si ile ẹjọ lori rẹ. "Bi ẹnikẹni ba gbe Secondus ati ẹgbẹ oṣelu PDP lọ sile ẹjọ, o di dandan, yoo farahan ni lati wi tẹnu rẹ. Awọn ọmọ Naijiria lo ni ẹgbẹ oṣelu yiio si tobi ju ẹnikẹni tabi ẹgbẹ kankan lọ titi kan awọn afipa du ipo". Yanponyanrin laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ti n waye baye fun osẹ diẹ eleyii ti awọn kan ninu ẹgbẹ naa ti gomina Nyesom Wike tipinlẹ Rivers ko sodi lati tun igbimọ isakoso ẹgbẹ naa ka. Iléẹjọ́ ní kí alága gbogboogbò PDP, Uche Secondus lọ rọọ́kùn nílé Rogbodiyan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ti fori sọ ibi kan kan lójọ Aje, lẹyin ti ileẹjọ giga ipinlẹ Rivers ni ki ni alaga gbogbo ẹgbẹ naa, Uche Secondus lọ rọkun nile na. Eeyan mẹrin, Ibeabuchi Ernest Alex, Dennis Nna Amadi, Emmanuel Stephen ati Umezirike Onucha lo ni ki ileẹjọ da Secondus duro gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ ọhun. Adajọ ileẹjọ giga ẹkun Degema, O. Gbasam sọ ninu idajọ rẹ pe aṣẹ gun ẹbẹ awọn mẹrin yii. Nkan ko fara rọ ninu ẹgbẹ PDP lori awuyewuye ati yọ Secondus nipo ṣaaju ipade gbogbogbo ẹgbẹ naa to n bọ lọna. Ẹwẹ, Secondus ti sọrọ lẹyin aṣẹ ile ẹjọ to ni ko gbọdọ pe ara rẹ ni alaga PDP mọ. Oludamọran Secondus lori ọrọ iroyin, Ike Abonyi sọ pe Secondus ṣetan lati sọ ti ẹnu rẹ ni ileẹjọ. O ni ẹgbẹ oṣelu PDP kii ṣe dukia ẹnikan, awọn ọmọ Naijiria lo ni i.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58313767
2health
Rauf Aregbesola sọ bó ṣe yẹ kí òbí máa fètò sọ́mọ bíbí
Minisita to n ri si ọrọ abẹle lorilede Naijiria to tun jẹ gomina ana ipinlẹ Osun, Ọgbẹni Rauf Aregbesola ti ni ki awọn obi din iye ọmọ ti wọn n bi ku. Aregbesola sọ eyi gẹgẹ bi ọkan lara awọn koko ọrọ to maa n fi sita lori ayelujara. O fi ọrọ rẹ gba awọn lọkọ-laya nimọran lati fi eto si bi wọn ṣe n bimọ nitori ipo ti orlẹede Naijiria wa lọwọlọwọ. Loju opo Twitter ti Ọgbẹni Aregbesola maa n lo fi kọ awọn koko ọrọ kekeke, o ni "a rọ awọn lọkọ-laya lati maa feto sọmọ bibi". Tani Akeredolu tó ń díje dupò gómìnà fún ìgbàkejì nípìnlẹ̀ Ondo? Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Eko fún Fayose lọ́jọ́ méje láti bẹ àwọn adarí ẹgbẹ́ Bí mo bá ṣáájú ìwọ́de ENDSAReS, kẹ́ẹ mọ̀ pé ẹ̀wọ̀n Kirikiri ni wọ́n á gbé mi lọ jàntò - Naira Marley O tẹnu mọ ọ pe "a ti n bimọ ju iye awọn ti orilẹede ṣetọju lọ. Torinaa, ọmọ meji si mẹta ti to". Aregbe ni o yẹ keeyan ṣe bo ṣe mọ ni, ẹlẹwa sapọn lori ọrọ ọmọ bibi lorilẹede Naijiria. Niwọnba iwọn iye owo tabi na atijẹ ti eeyan ni ni Ọgbẹni Aregbesola ni o yẹ keeyan wo ko to maa ka ọmọ jọ.
Rauf Aregbesola sọ bó ṣe yẹ kí òbí máa fètò sọ́mọ bíbí Minisita to n ri si ọrọ abẹle lorilede Naijiria to tun jẹ gomina ana ipinlẹ Osun, Ọgbẹni Rauf Aregbesola ti ni ki awọn obi din iye ọmọ ti wọn n bi ku. Aregbesola sọ eyi gẹgẹ bi ọkan lara awọn koko ọrọ to maa n fi sita lori ayelujara. O fi ọrọ rẹ gba awọn lọkọ-laya nimọran lati fi eto si bi wọn ṣe n bimọ nitori ipo ti orlẹede Naijiria wa lọwọlọwọ. Loju opo Twitter ti Ọgbẹni Aregbesola maa n lo fi kọ awọn koko ọrọ kekeke, o ni "a rọ awọn lọkọ-laya lati maa feto sọmọ bibi". Tani Akeredolu tó ń díje dupò gómìnà fún ìgbàkejì nípìnlẹ̀ Ondo? Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Eko fún Fayose lọ́jọ́ méje láti bẹ àwọn adarí ẹgbẹ́ Bí mo bá ṣáájú ìwọ́de ENDSAReS, kẹ́ẹ mọ̀ pé ẹ̀wọ̀n Kirikiri ni wọ́n á gbé mi lọ jàntò - Naira Marley O tẹnu mọ ọ pe "a ti n bimọ ju iye awọn ti orilẹede ṣetọju lọ. Torinaa, ọmọ meji si mẹta ti to". Aregbe ni o yẹ keeyan ṣe bo ṣe mọ ni, ẹlẹwa sapọn lori ọrọ ọmọ bibi lorilẹede Naijiria. Niwọnba iwọn iye owo tabi na atijẹ ti eeyan ni ni Ọgbẹni Aregbesola ni o yẹ keeyan wo ko to maa ka ọmọ jọ.
https://www.bbc.com/yoruba/54417215
5sports
Anthony Joshua: Lẹ́yìn ìjà rẹ̀ pẹ̀lú Luiz, Anthony Joshua bẹ Ọba ìlú rẹ̀, Àkárìgbò wò
Ṣe awọn agba bọ wọn ni ọmọ ale ni fi ọwọ osi juwe ile baba rẹ. Gbajugbaja akanṣẹ lagbaye, Anthony Joshua bẹ ile wo lọjọru. Taara ta ilu rẹ ni Ṣagamu lo mori le, nibẹ lo si ti ṣe baba kẹẹ pẹ sawọn ọbalaye ati oriade gbogbo to wa nilu naa. Eyi ni igba akọkọ ti Anthony Joshua yoo maa yọju si orilẹede Naijiria lẹyin to gba igbanu ẹyẹ agbaye rẹ, WBA, WBO, IBF ati IBO pada lọwọ Andy Ruiz. Ọmọ orilẹede Mexico naa si lo gba ami ẹyẹ ọhun dani fun bi oṣu diẹ, nibi ija wọn to waye ni gbagede Diriyah Arena lorilẹede Saudi Arabia. Ọkẹ aimoye awọn ololufẹ rẹ ni wọn rọgba yii ka lasiko to fi lọ ki Alafin Ẹlẹpẹ ati Akarigbo ti ilẹ Rẹmọ ni aafin wọn. Lẹyin to foribalẹ fawọn ọba alade naa tan, ni Anthony Joshua wa ya fọto pẹlu awọn ololufẹ rẹ ti wọn wa foju gaanni rẹ. Ariwo 'ibi ni ile rẹ kii ṣe ilẹ Gẹẹsi' ni ọpọlọpọ awọn eeyan to tu sita wa wo agba ọjẹ akanṣẹ naa n pa, bi gbogbo wọn ṣe n da giiri lati baa ya fọto, ti wọn si tun wọ tọọ lẹyin lati aafin Elepe lọ si aafin Kabiyesi Akarigbo ti ilu Rẹmọ.
Anthony Joshua: Lẹ́yìn ìjà rẹ̀ pẹ̀lú Luiz, Anthony Joshua bẹ Ọba ìlú rẹ̀, Àkárìgbò wò Ṣe awọn agba bọ wọn ni ọmọ ale ni fi ọwọ osi juwe ile baba rẹ. Gbajugbaja akanṣẹ lagbaye, Anthony Joshua bẹ ile wo lọjọru. Taara ta ilu rẹ ni Ṣagamu lo mori le, nibẹ lo si ti ṣe baba kẹẹ pẹ sawọn ọbalaye ati oriade gbogbo to wa nilu naa. Eyi ni igba akọkọ ti Anthony Joshua yoo maa yọju si orilẹede Naijiria lẹyin to gba igbanu ẹyẹ agbaye rẹ, WBA, WBO, IBF ati IBO pada lọwọ Andy Ruiz. Ọmọ orilẹede Mexico naa si lo gba ami ẹyẹ ọhun dani fun bi oṣu diẹ, nibi ija wọn to waye ni gbagede Diriyah Arena lorilẹede Saudi Arabia. Ọkẹ aimoye awọn ololufẹ rẹ ni wọn rọgba yii ka lasiko to fi lọ ki Alafin Ẹlẹpẹ ati Akarigbo ti ilẹ Rẹmọ ni aafin wọn. Lẹyin to foribalẹ fawọn ọba alade naa tan, ni Anthony Joshua wa ya fọto pẹlu awọn ololufẹ rẹ ti wọn wa foju gaanni rẹ. Ariwo 'ibi ni ile rẹ kii ṣe ilẹ Gẹẹsi' ni ọpọlọpọ awọn eeyan to tu sita wa wo agba ọjẹ akanṣẹ naa n pa, bi gbogbo wọn ṣe n da giiri lati baa ya fọto, ti wọn si tun wọ tọọ lẹyin lati aafin Elepe lọ si aafin Kabiyesi Akarigbo ti ilu Rẹmọ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51569245
2health
Myrtle Corbin: Obìnrin tó ló àìdàpé ara rẹ̀, sọ ara rẹ̀ di olówó
Yoruba ni ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin, bẹẹ si ni tibi tire la dale aye, tibi tire la se ẹda eeyan, bi ire se wa ninu ibi, naa ni ibi wa ninu ire. Bi ọrọ igbe aye arabinrin kan se ri ree, ẹni ti o ni aidape ara amọ ti ọba oke se e ni ogo pẹlu aidape ara naa. Eyi si lo fidi rẹ mulẹ pe agbara wa ninu aidape ara, ta ba si lero pe Oluwa n se ibi, ase rere lo n se. Arabinrin naa, Josephine Myrtle Corbin, lo ni ẹsẹ mẹrin, ile ọmọ meji, oju ara meji amọ ti ọba oke tun fun ni agbara lati bi ọmọ mẹjọ nile aye. Gẹgẹ ba se ka loju opo Wikipedia, asise atọrunwa waye lasiko ti wọn loyun arabinrin naa, eyi to fa aidape ara fun. Bi igbe aye rẹ si se lọ ree eyi to yẹ ka fi se arikọgbọn. Igba iloyun ati ibẹrẹ aye Myrtle Corbin: Orukọ baba Myrtle Cobin ni William H. Corbin, tii se ẹni ọdun mẹẹdọgbọn nigba to fun aya rẹ, Nancy Corbin, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn loyun. Agbegbe Lincoln County, nilu Tennessee lorilẹede Amẹrika ni awọn obi Myrtle Corbin n gbe lakoko ti wọn loyun rẹ. Lọjọ ti ọmọ tuntun naa de ile aye ni ọjọ Karun, osu Kejila ọdun 1868, ni wọn ri pe ibeji lo fẹ wa saye amọ ti ikeji rẹ ko lagbara lati di odidi eeyan, to si jẹ aabọ ẹda to so mọ ekeji rẹ lara. Ẹsẹ mejeeji to yẹ ko jẹ ti ekeji rẹ ti ko pe odidi ẹda, ni Myrtle Corbin papọ, ti ẹsẹ rẹ fi di mẹrin, to fi mọ ile ọmọ ati oju ara ekeji rẹ lo dapọ mọ tiẹ, to fi di meji-meji fun. Nigba ti wọn bi Myrtle Corbin pẹlu abuku ara yii, ẹnu ya awọn dokita, ti wọn si ri pe o dabu sinu iya rẹ ni, amọ wọn yi ipo to wa pada, to fi rọrun lati bii, bibẹẹ kọ ọrun ni aala fun tiya-tọmọ. Nigba ti wọn bi ọmọ yii, ko tii si isẹ abẹ rara lasiko naa lati gba ẹbi alaboyun tabi fi ya ibeji to lẹpọ. Idi ree ti isẹda Myrtle Corbin fi se ara ọtọ lasiko ti wọn bi, ti ko si si ireti fun lati gbe ile aye. Amọ riro ni ti eniyan, sise ni ti Ọlọrun, ọmọ naa n dagba, eegun rẹ si n le bii ti ọmọ to dape, bẹẹ lo n dagba ni ẹmi ati ni ọpọlọ. Bawo lo se rọrun fun Myrtle Corbin lati gbe ile aye? Awọn dokita si ri pe lati ibi ibadi ni ẹsẹ ikeji Myrtle Corbin ti so pọ mọ tiẹ, to si ni ara meji lati ibadi wa si isalẹ, eyi to mu ko tun ni oju ara ati ile ọmọ meji pẹlu. Amọ o rọrun fun obinrin naa lati se akoso ẹsẹ ekeji rẹ naa, nitori ko gun to awọn ẹsẹ tiẹ mejeejiy, eyi to mu ko ma subu lasiko to ba n fi n rin. Idi ni pe awọn ẹsẹ mejeeji ekeji rẹ naa lo wa ni aarin, ti wọn ko si ni agbara ra tabi ni imi ninu, ti ko si se fi rin rara. Bakan naa, ọmọ ika ẹsẹ mẹta pere lo wa lara ẹsẹ ekeji rẹ naa. Awọn ara ti Myrtle Corbin fi abuku ara rẹ da, to sọ di olowo: Arẹwa pọnbele ni Myrtle Corbin, ti ọba oke si fi ẹwa jinki rẹ lai naani abuku ara yii. Koda, obinrin giga ni, iwọn giga rẹ si jẹ ẹsẹ bata marun, o mọ lawọ, o ni ọpọlọpọ irun lori, to si tun ni oju buluu. Nigba to di ẹni ọdun mẹtala, okiki obinrin naa ti kan yika agbaye nipa ọna to n gba mura, eyi to ya ni lẹnu pupọ. Baba obinrin yii lo kọkọ ronu nipa ọna ti yoo fi wulo, to si bẹrẹ si patẹ rẹ ni awọn gbọngan sinima, ti ọpọ eeyan si n ya wa fi owo ribiribi wo akanda ẹda obinrin ẹlẹsẹ mẹrin naa. Se ni Myrtle Corbin si n lo abuku ara rẹ lati fi pa owo nipa imura rẹ. Yoo si wọ awọn ọmọ ika ẹsẹ rẹ ti ko dape naa ni asọ ti oyinbo n pe ni socks. Bakan naa ni yoo wọ bata fun awọn ẹsẹ ekeji rẹ to wa ni aarin ẹsẹ tiẹ, bi o tilẹ jẹ pe kii fi awọn ẹsẹ naa rin. Nigba to ya, awọn eeyan to jẹ gbajumọ ninu isẹ amuludun bii P.T Barnum, Ringling bros ati Coney Island n ba Myrtle dowo pọ, ti wọn si n gbe isẹ afihan ara rẹ to n se larugẹ. Okiki Myrtle Corbin si tan debi pe o n pa owo to to ọtalenirinwo o din mẹwa dọla ($450) ni ọsẹ kan, eyi to jẹ owo nla nigba naa. Nigba to pe ẹni ọdun mọkandinlogun, Myrtle Corbin se igbeyawo pẹlu James Clinton Bicknell, ẹni to pọn ni dandan fun aya rẹ lati mase patẹ aidape ara rẹ fun aye mọ. Awọn mejeeji bẹrẹ isẹ oko dida ti ọkọ rẹ n se tẹlẹ, eyi to fihan pe ifẹ tootọ ni James ni si Myrtle, kii si se tori owo ti obinrin naa ni, lo se fẹ. Amọ lẹyin igbeyawo wọn ni ọkọ rẹ ri pe oju ara meji ni Myrtle ni, ti oju ara keji si jẹ ti ibeji rẹ, eyi to mu ki obinrin naa jẹ obinrin kan soso lagbaye ti yoo ni oju ara meji. Bakan naa, nigba to loyun ni asiri tu sọwọ awọn dokita pe ile ọmọ meji naa tun ni obinrin aramọnda yii ni, to si fi ile ọmọ apa osi loyun. Lẹyin o rẹyin, ọmọ mẹjọ ni Myrtle Cobin bi sile aye amọ mẹta pere lo gbẹyin rẹ. Nigba to di ọdun 1928, ti Myrtle Corbin pe ẹni ọgọta ọdun ni aisan ara kan kọlu u, eyi to ba awọ rẹ jẹ, ti ko si gbọ wiwo. Lasiko yii, ko tii si iwosan fun arun ara naa ti wọn n pe ni Erysipelas, a streptococcal skin infection, amọ lode toni, horo oogun diẹ ti to lati wo aisan naa. Nigba to di ọjọ Kẹfa, osu Karun ọdun 1928, Josephine Myrtle Corbin-Bicknell jade laye nilu Cleburne nipinlẹ Texas, eyi to fi opin si igbe aye obinrin kan soso to ni ẹsẹ mẹrin. Se ni awọn mọlẹbi rẹ si n sọ oku ati posi rẹ lọwọ-lẹsẹ, ki awọn adigunjale maa baa ji gbe salọ. Koda, awọn onisẹ iwadii, afi nnkan isẹmbaye pamọ atawọn onisegun oyinbo gan gbe owo kalẹ lati gba oku rẹ amọ awọn mọlẹbi rẹ taku, ti wọn si tubọ n sọ oku rẹ. Ẹkọ akọkọ ti itan aye Myrtle Corbin kọ wa ni pe ka ma jẹ ki aidape tabi abuku ara di wa lọwọ lati mase gbe ohun rere se nile aye. Ẹkọ keji ni pe igbe aye Myrtle Corbin kọ wa lati mase jẹ ki ipo ta n la kọja se akoso aye wa nitori igba ko tọ lọ bii orere, aye ko tọ lọ bi ọpa ibọn. Myrtle Corbin jẹ alabuku ara amọ eyi ko ni ko ma de ibi giga nile aye , o ni ẹkunrẹrẹ ayọ ati ohun amuyangan, eyi to yẹ ki awa naa fi se awokọse rere. Lakotan, igbe aye Myrtle Corbin kọ wa lati ni ifarada, ipamọra ati ifiraẹnijin ni ipokupo ti a ba wa nitori ohun gbogbo lo n sisẹ pọ fun rere.
Myrtle Corbin: Obìnrin tó ló àìdàpé ara rẹ̀, sọ ara rẹ̀ di olówó Yoruba ni ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin, bẹẹ si ni tibi tire la dale aye, tibi tire la se ẹda eeyan, bi ire se wa ninu ibi, naa ni ibi wa ninu ire. Bi ọrọ igbe aye arabinrin kan se ri ree, ẹni ti o ni aidape ara amọ ti ọba oke se e ni ogo pẹlu aidape ara naa. Eyi si lo fidi rẹ mulẹ pe agbara wa ninu aidape ara, ta ba si lero pe Oluwa n se ibi, ase rere lo n se. Arabinrin naa, Josephine Myrtle Corbin, lo ni ẹsẹ mẹrin, ile ọmọ meji, oju ara meji amọ ti ọba oke tun fun ni agbara lati bi ọmọ mẹjọ nile aye. Gẹgẹ ba se ka loju opo Wikipedia, asise atọrunwa waye lasiko ti wọn loyun arabinrin naa, eyi to fa aidape ara fun. Bi igbe aye rẹ si se lọ ree eyi to yẹ ka fi se arikọgbọn. Igba iloyun ati ibẹrẹ aye Myrtle Corbin: Orukọ baba Myrtle Cobin ni William H. Corbin, tii se ẹni ọdun mẹẹdọgbọn nigba to fun aya rẹ, Nancy Corbin, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn loyun. Agbegbe Lincoln County, nilu Tennessee lorilẹede Amẹrika ni awọn obi Myrtle Corbin n gbe lakoko ti wọn loyun rẹ. Lọjọ ti ọmọ tuntun naa de ile aye ni ọjọ Karun, osu Kejila ọdun 1868, ni wọn ri pe ibeji lo fẹ wa saye amọ ti ikeji rẹ ko lagbara lati di odidi eeyan, to si jẹ aabọ ẹda to so mọ ekeji rẹ lara. Ẹsẹ mejeeji to yẹ ko jẹ ti ekeji rẹ ti ko pe odidi ẹda, ni Myrtle Corbin papọ, ti ẹsẹ rẹ fi di mẹrin, to fi mọ ile ọmọ ati oju ara ekeji rẹ lo dapọ mọ tiẹ, to fi di meji-meji fun. Nigba ti wọn bi Myrtle Corbin pẹlu abuku ara yii, ẹnu ya awọn dokita, ti wọn si ri pe o dabu sinu iya rẹ ni, amọ wọn yi ipo to wa pada, to fi rọrun lati bii, bibẹẹ kọ ọrun ni aala fun tiya-tọmọ. Nigba ti wọn bi ọmọ yii, ko tii si isẹ abẹ rara lasiko naa lati gba ẹbi alaboyun tabi fi ya ibeji to lẹpọ. Idi ree ti isẹda Myrtle Corbin fi se ara ọtọ lasiko ti wọn bi, ti ko si si ireti fun lati gbe ile aye. Amọ riro ni ti eniyan, sise ni ti Ọlọrun, ọmọ naa n dagba, eegun rẹ si n le bii ti ọmọ to dape, bẹẹ lo n dagba ni ẹmi ati ni ọpọlọ. Bawo lo se rọrun fun Myrtle Corbin lati gbe ile aye? Awọn dokita si ri pe lati ibi ibadi ni ẹsẹ ikeji Myrtle Corbin ti so pọ mọ tiẹ, to si ni ara meji lati ibadi wa si isalẹ, eyi to mu ko tun ni oju ara ati ile ọmọ meji pẹlu. Amọ o rọrun fun obinrin naa lati se akoso ẹsẹ ekeji rẹ naa, nitori ko gun to awọn ẹsẹ tiẹ mejeejiy, eyi to mu ko ma subu lasiko to ba n fi n rin. Idi ni pe awọn ẹsẹ mejeeji ekeji rẹ naa lo wa ni aarin, ti wọn ko si ni agbara ra tabi ni imi ninu, ti ko si se fi rin rara. Bakan naa, ọmọ ika ẹsẹ mẹta pere lo wa lara ẹsẹ ekeji rẹ naa. Awọn ara ti Myrtle Corbin fi abuku ara rẹ da, to sọ di olowo: Arẹwa pọnbele ni Myrtle Corbin, ti ọba oke si fi ẹwa jinki rẹ lai naani abuku ara yii. Koda, obinrin giga ni, iwọn giga rẹ si jẹ ẹsẹ bata marun, o mọ lawọ, o ni ọpọlọpọ irun lori, to si tun ni oju buluu. Nigba to di ẹni ọdun mẹtala, okiki obinrin naa ti kan yika agbaye nipa ọna to n gba mura, eyi to ya ni lẹnu pupọ. Baba obinrin yii lo kọkọ ronu nipa ọna ti yoo fi wulo, to si bẹrẹ si patẹ rẹ ni awọn gbọngan sinima, ti ọpọ eeyan si n ya wa fi owo ribiribi wo akanda ẹda obinrin ẹlẹsẹ mẹrin naa. Se ni Myrtle Corbin si n lo abuku ara rẹ lati fi pa owo nipa imura rẹ. Yoo si wọ awọn ọmọ ika ẹsẹ rẹ ti ko dape naa ni asọ ti oyinbo n pe ni socks. Bakan naa ni yoo wọ bata fun awọn ẹsẹ ekeji rẹ to wa ni aarin ẹsẹ tiẹ, bi o tilẹ jẹ pe kii fi awọn ẹsẹ naa rin. Nigba to ya, awọn eeyan to jẹ gbajumọ ninu isẹ amuludun bii P.T Barnum, Ringling bros ati Coney Island n ba Myrtle dowo pọ, ti wọn si n gbe isẹ afihan ara rẹ to n se larugẹ. Okiki Myrtle Corbin si tan debi pe o n pa owo to to ọtalenirinwo o din mẹwa dọla ($450) ni ọsẹ kan, eyi to jẹ owo nla nigba naa. Nigba to pe ẹni ọdun mọkandinlogun, Myrtle Corbin se igbeyawo pẹlu James Clinton Bicknell, ẹni to pọn ni dandan fun aya rẹ lati mase patẹ aidape ara rẹ fun aye mọ. Awọn mejeeji bẹrẹ isẹ oko dida ti ọkọ rẹ n se tẹlẹ, eyi to fihan pe ifẹ tootọ ni James ni si Myrtle, kii si se tori owo ti obinrin naa ni, lo se fẹ. Amọ lẹyin igbeyawo wọn ni ọkọ rẹ ri pe oju ara meji ni Myrtle ni, ti oju ara keji si jẹ ti ibeji rẹ, eyi to mu ki obinrin naa jẹ obinrin kan soso lagbaye ti yoo ni oju ara meji. Bakan naa, nigba to loyun ni asiri tu sọwọ awọn dokita pe ile ọmọ meji naa tun ni obinrin aramọnda yii ni, to si fi ile ọmọ apa osi loyun. Lẹyin o rẹyin, ọmọ mẹjọ ni Myrtle Cobin bi sile aye amọ mẹta pere lo gbẹyin rẹ. Nigba to di ọdun 1928, ti Myrtle Corbin pe ẹni ọgọta ọdun ni aisan ara kan kọlu u, eyi to ba awọ rẹ jẹ, ti ko si gbọ wiwo. Lasiko yii, ko tii si iwosan fun arun ara naa ti wọn n pe ni Erysipelas, a streptococcal skin infection, amọ lode toni, horo oogun diẹ ti to lati wo aisan naa. Nigba to di ọjọ Kẹfa, osu Karun ọdun 1928, Josephine Myrtle Corbin-Bicknell jade laye nilu Cleburne nipinlẹ Texas, eyi to fi opin si igbe aye obinrin kan soso to ni ẹsẹ mẹrin. Se ni awọn mọlẹbi rẹ si n sọ oku ati posi rẹ lọwọ-lẹsẹ, ki awọn adigunjale maa baa ji gbe salọ. Koda, awọn onisẹ iwadii, afi nnkan isẹmbaye pamọ atawọn onisegun oyinbo gan gbe owo kalẹ lati gba oku rẹ amọ awọn mọlẹbi rẹ taku, ti wọn si tubọ n sọ oku rẹ. Ẹkọ akọkọ ti itan aye Myrtle Corbin kọ wa ni pe ka ma jẹ ki aidape tabi abuku ara di wa lọwọ lati mase gbe ohun rere se nile aye. Ẹkọ keji ni pe igbe aye Myrtle Corbin kọ wa lati mase jẹ ki ipo ta n la kọja se akoso aye wa nitori igba ko tọ lọ bii orere, aye ko tọ lọ bi ọpa ibọn. Myrtle Corbin jẹ alabuku ara amọ eyi ko ni ko ma de ibi giga nile aye , o ni ẹkunrẹrẹ ayọ ati ohun amuyangan, eyi to yẹ ki awa naa fi se awokọse rere. Lakotan, igbe aye Myrtle Corbin kọ wa lati ni ifarada, ipamọra ati ifiraẹnijin ni ipokupo ti a ba wa nitori ohun gbogbo lo n sisẹ pọ fun rere.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58370341
3politics
Ṣé lóòótọ́ ni Tinubu ń pín #30,000 fún àwọn ènìyàn?
Ẹgbẹ oṣelu APC ti ki kede pe atẹjisẹ kan to gba ori ayelujara kan pe oludije aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu n pin ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira fun awọn eeyan ni o jẹ iro nla ati pe iroyin ofege ni. Atẹjisẹ ọhun ni awọn kan kọ ni ede Hausa, ti wọn si n pe awọn eeyan lati wa si agbegbe kan lati wa gba owo ti n ẹgbẹ iponlogo Tinubu/Shettima n pin fun awọn eeyan. Lati ninu oṣu kọkanla ni atẹjisẹ ọhun ti n tan kiri lori ayelujara, ti awọn si n pin kiri fun awọ0n eeyan wọn yoku lori ikan ibanisọrọ Whatsapp.\nAtẹjisẹ naa ni akọle "Tinubu/Shettima dun awọn ọmọ Naijiria ni N30,000 lati fi ponlogo ibo fun ohun." "Ẹ ma bọ lati ki ẹ wa wo boya orukọ yin wa lara awọn ti yoo gbe N30,000 lati lọwọ Tinubu." Gẹgẹ bii wọn ṣe lọdun 2015 ati 2019, ẹgbẹ oṣelu APC ti kede pe awọn nilo iranlọwọ owo lati ọdọ awọn ọmọ Naijiria saaju eto idibo ọdun 2023.\nAwọn alaatilẹyin ẹgbẹ oṣelu naa, to fi jẹ, oluranlọwọ aarẹ lori ayelujara, Bashir Ahmed, ti bọ si ori ayelujara ni ọpọ igba lati bere fun iranlọwọ lọwọ awọn ọmọ Naijria, Ẹgbẹ iponlogo Tinubu/Shettima fi nomba banki sita fun awọn to ba fẹ ran wọn lọwọ lati fi owo si ibẹ "Ẹ ran wa lọwọ lati mu ileri wa si imusẹ lori orilẹede Naijria." Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ iponlogo ibo Tinubu/Shettima fi tako atẹjisẹ naa ni iro nla ni, ti ko si ti ọdọ awọn wa rara. Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Festus Kayemo ni awọn ẹgbẹ alatako ni wọn wa gbogbo ọna lati ṣe akoba fun ẹgbẹ oṣelu APC saaju eto idibo lọdun 2023. "A ri atẹjisẹ ọhun sugbọn ọdọ wa ko lo ti jade." "Awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lo n gbe awọn igbesẹ lati fi tan awọn ọmọ orilẹede Naijria."
Ṣé lóòótọ́ ni Tinubu ń pín #30,000 fún àwọn ènìyàn? Ẹgbẹ oṣelu APC ti ki kede pe atẹjisẹ kan to gba ori ayelujara kan pe oludije aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu n pin ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira fun awọn eeyan ni o jẹ iro nla ati pe iroyin ofege ni. Atẹjisẹ ọhun ni awọn kan kọ ni ede Hausa, ti wọn si n pe awọn eeyan lati wa si agbegbe kan lati wa gba owo ti n ẹgbẹ iponlogo Tinubu/Shettima n pin fun awọn eeyan. Lati ninu oṣu kọkanla ni atẹjisẹ ọhun ti n tan kiri lori ayelujara, ti awọn si n pin kiri fun awọ0n eeyan wọn yoku lori ikan ibanisọrọ Whatsapp.\nAtẹjisẹ naa ni akọle "Tinubu/Shettima dun awọn ọmọ Naijiria ni N30,000 lati fi ponlogo ibo fun ohun." "Ẹ ma bọ lati ki ẹ wa wo boya orukọ yin wa lara awọn ti yoo gbe N30,000 lati lọwọ Tinubu." Gẹgẹ bii wọn ṣe lọdun 2015 ati 2019, ẹgbẹ oṣelu APC ti kede pe awọn nilo iranlọwọ owo lati ọdọ awọn ọmọ Naijiria saaju eto idibo ọdun 2023.\nAwọn alaatilẹyin ẹgbẹ oṣelu naa, to fi jẹ, oluranlọwọ aarẹ lori ayelujara, Bashir Ahmed, ti bọ si ori ayelujara ni ọpọ igba lati bere fun iranlọwọ lọwọ awọn ọmọ Naijria, Ẹgbẹ iponlogo Tinubu/Shettima fi nomba banki sita fun awọn to ba fẹ ran wọn lọwọ lati fi owo si ibẹ "Ẹ ran wa lọwọ lati mu ileri wa si imusẹ lori orilẹede Naijria." Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ iponlogo ibo Tinubu/Shettima fi tako atẹjisẹ naa ni iro nla ni, ti ko si ti ọdọ awọn wa rara. Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Festus Kayemo ni awọn ẹgbẹ alatako ni wọn wa gbogbo ọna lati ṣe akoba fun ẹgbẹ oṣelu APC saaju eto idibo lọdun 2023. "A ri atẹjisẹ ọhun sugbọn ọdọ wa ko lo ti jade." "Awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lo n gbe awọn igbesẹ lati fi tan awọn ọmọ orilẹede Naijria."
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cd19m12e7jgo
1entertainment
Nollywood: Wo àkójọpọ̀ ohun tó wáyé lágbo àwọn òṣèré tíátà lọ́sẹ̀ yìí
Oniruuru awọn isẹlẹ nla nla lo waye ni agbo awọn osere tiata lọsẹ yii ti ko yẹ kẹ padanu rẹ. Bi awọn isẹlẹ kan se dun mọ ni ninu, ni awọn kan ba ni lkan jẹ, se tibi tire la da ile aye. Awọn akojọpọ isẹlẹ to waye lagbo tiata lọsẹ yii re ni sisẹ n tẹle. Ori lo mọ iṣẹ aṣela laye. Bolaji Amusan ti ọpọ mọ si Mr Latin ati Odunlade Adekola lọ si ilu oyinbo niluu Vienna lorilẹede Austria nibi ayẹyẹ kanifa aṣọ Adire. Mr Latin lo fi fọto oun ati Adekola nibi ti wọn ti wọ aṣọ Adire nibi ayẹyẹ ọhun niluu Vienna si ori ẹrọ Instagram. MR Latin tiẹ sọ loju opo Instagram rẹ pe "ẹ o tii ri nkan kan", eyi to tumọ si pe wọn sẹsẹ n mu ẹyẹ bọ lapo ni. Ori arabinrin kan lo ma ti sọre bayii lẹyin to ya "tattoo" Okuneye Olanrewaju Idris, ti ọpọ mọ si Bobrisky si ara rẹ. Bobrisky funra rẹ lo fi fọto obinrin naa, to jẹ ọkan lara awọn ololufẹ rẹ si oju opo Instagram rẹ pẹlu "tattoo" to ya si ẹyin rẹ. Bobrisky wa ṣeleri lati ṣe ohun mere-mere fun arabinrin naa. O ṣeleri lati fun obinrin ọhún l'ẹbun miliọnu kan naira, ra foonu to ba fẹ fun un ati pe, oun maa gbe arabinrin naa rinrin ajo afẹ lọ si Dubai. Dokita fun Kemi Afolabi ni oogun oorun lati fara nisinmi lẹyin ayẹyẹ isile rẹ: Lẹyin to ṣe ayẹyẹ iṣile tan, oṣere tiata Yoruba, Kemi Afolabi wa ni igbele nibi ti o ti n sinmi. O ni awọn dokita lo sọ foun pe oun nilo lati sinmi nile tori ilera ara oun. Kemi ni oun ko mọ pe awọn dokita oun fi oogun orun sinu abẹrẹ ti wọn fún oun. Iku doro, iku ṣeka, iku ti mu Lofty Eyiwumi Ray to jẹ aburo gbajugbaja oṣere Mukaddam Eyiwumi Ray ti ọpọ mọ sí Muka Ray lọ. Loju opo Instagram rẹ ni Muka Ray ti sọ nipa iku aburo rẹ obinrin yii. Ibeere "ki lo de, ki lo ṣẹlẹ" ni Muka Ray n beere pẹlu ẹdun ọkan lori oju opo Instagram rẹ. Bakan naa lo fi ọrọ bii "sun re o, o daarọ si ori Instagram rẹ eyi to fi dagbere fun aburo rẹ to ṣe aláìsi.
Nollywood: Wo àkójọpọ̀ ohun tó wáyé lágbo àwọn òṣèré tíátà lọ́sẹ̀ yìí Oniruuru awọn isẹlẹ nla nla lo waye ni agbo awọn osere tiata lọsẹ yii ti ko yẹ kẹ padanu rẹ. Bi awọn isẹlẹ kan se dun mọ ni ninu, ni awọn kan ba ni lkan jẹ, se tibi tire la da ile aye. Awọn akojọpọ isẹlẹ to waye lagbo tiata lọsẹ yii re ni sisẹ n tẹle. Ori lo mọ iṣẹ aṣela laye. Bolaji Amusan ti ọpọ mọ si Mr Latin ati Odunlade Adekola lọ si ilu oyinbo niluu Vienna lorilẹede Austria nibi ayẹyẹ kanifa aṣọ Adire. Mr Latin lo fi fọto oun ati Adekola nibi ti wọn ti wọ aṣọ Adire nibi ayẹyẹ ọhun niluu Vienna si ori ẹrọ Instagram. MR Latin tiẹ sọ loju opo Instagram rẹ pe "ẹ o tii ri nkan kan", eyi to tumọ si pe wọn sẹsẹ n mu ẹyẹ bọ lapo ni. Ori arabinrin kan lo ma ti sọre bayii lẹyin to ya "tattoo" Okuneye Olanrewaju Idris, ti ọpọ mọ si Bobrisky si ara rẹ. Bobrisky funra rẹ lo fi fọto obinrin naa, to jẹ ọkan lara awọn ololufẹ rẹ si oju opo Instagram rẹ pẹlu "tattoo" to ya si ẹyin rẹ. Bobrisky wa ṣeleri lati ṣe ohun mere-mere fun arabinrin naa. O ṣeleri lati fun obinrin ọhún l'ẹbun miliọnu kan naira, ra foonu to ba fẹ fun un ati pe, oun maa gbe arabinrin naa rinrin ajo afẹ lọ si Dubai. Dokita fun Kemi Afolabi ni oogun oorun lati fara nisinmi lẹyin ayẹyẹ isile rẹ: Lẹyin to ṣe ayẹyẹ iṣile tan, oṣere tiata Yoruba, Kemi Afolabi wa ni igbele nibi ti o ti n sinmi. O ni awọn dokita lo sọ foun pe oun nilo lati sinmi nile tori ilera ara oun. Kemi ni oun ko mọ pe awọn dokita oun fi oogun orun sinu abẹrẹ ti wọn fún oun. Iku doro, iku ṣeka, iku ti mu Lofty Eyiwumi Ray to jẹ aburo gbajugbaja oṣere Mukaddam Eyiwumi Ray ti ọpọ mọ sí Muka Ray lọ. Loju opo Instagram rẹ ni Muka Ray ti sọ nipa iku aburo rẹ obinrin yii. Ibeere "ki lo de, ki lo ṣẹlẹ" ni Muka Ray n beere pẹlu ẹdun ọkan lori oju opo Instagram rẹ. Bakan naa lo fi ọrọ bii "sun re o, o daarọ si ori Instagram rẹ eyi to fi dagbere fun aburo rẹ to ṣe aláìsi.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-55855905
1entertainment
Naira Marley: Pásítọ̀ Omatsola tún kìlọ̀ fáwọn ọ̀dọ́ láti yé pe ara wọn ní Marlians
Gbajugbaja olorin takasufe, Afeez Fashola ti ọpọ eeyan mọ si Naira Marley, ti fesi si ọrọ Pasitọ Chris Omashola to pe ni ẹlẹmi Eṣu. Ojiṣẹ Ọlọrun naa ti sọ tẹlẹ pe, Ọlọrun lo fi iran han oun pe ẹlẹmi Eṣu ni Naira Marley. Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ @omo_billionaire loju opo Twitter, lo bi awọn eeyan leere pe kin ni idajọ lori ọrọ pasitọ Omashola ati Naira Marley. Lẹyin naa ni Naira Marley funra rẹ fi ọrọ kan naa lede loju opo Twitter tiẹ naa. Ṣugbọn orin ni Naira Marley fi fesi si ọrọ yii lẹyin to sọ pe ''Se bi omo jesu niwo, gbese ko Tesumole 🎶.'' Ero ọpọlọpọ awọn ololufẹ Naira Marley lo jọra wọn lori ọrọ naa, n ṣe ni awọn naa fi orin ''Se bi omo jesu niwo, gbese ko Tesumole 🎶'' bọ ẹnu ni idahun wọn si esi Naira Marley. Amọ, ero awọn kan ṣọtọọtọ lori ọrọ naa, fun apẹrẹ, @funshi ni oniyẹyẹ ni pasitọ Omashola, o ni pasitọ naa ko riran pe Fashola Azeez lẹmi Eṣu. Ẹlomiran, @mubaraq_a tun kin ọrọ @funshi lẹyin, o ni Naira Marley nikan ni Ọlọrun fihan ojiṣẹ Ọlọrun naa. Epe rabandẹ lawọn kan tiẹ n fi ranṣẹ si pasitọ Omashola, wọn ni ko mọ ohun to n sọ. Laipẹ yii ni Pasitọ Omashola sọrọ loju opo Twitter rẹ, nibi ti o ti kọ orukọ awọn eeyan to ro pe wọn ko le wọ ijọba ọrun ninu eyi ti Naira Marley wa loke tente. Pasitọ Omoshola fikun ọrọ rẹ pe Naira Marley ni lati ronu piwada ni kiakia ko too pẹ fun un. O ni awọn orin ti Naira Marley n kọ ni imisi Eṣu ninu, eyi to le ṣakoba fun ọjọ iwaju ati ayanmọ awọn ọdọ ni Naijira. Bakan naa ni ojiṣẹ Ọlọrun Omoshola kilọ fawọn ọdọ wi pe, ki wọn ye pe ara wọn ni ''Marlians.''
Naira Marley: Pásítọ̀ Omatsola tún kìlọ̀ fáwọn ọ̀dọ́ láti yé pe ara wọn ní Marlians Gbajugbaja olorin takasufe, Afeez Fashola ti ọpọ eeyan mọ si Naira Marley, ti fesi si ọrọ Pasitọ Chris Omashola to pe ni ẹlẹmi Eṣu. Ojiṣẹ Ọlọrun naa ti sọ tẹlẹ pe, Ọlọrun lo fi iran han oun pe ẹlẹmi Eṣu ni Naira Marley. Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ @omo_billionaire loju opo Twitter, lo bi awọn eeyan leere pe kin ni idajọ lori ọrọ pasitọ Omashola ati Naira Marley. Lẹyin naa ni Naira Marley funra rẹ fi ọrọ kan naa lede loju opo Twitter tiẹ naa. Ṣugbọn orin ni Naira Marley fi fesi si ọrọ yii lẹyin to sọ pe ''Se bi omo jesu niwo, gbese ko Tesumole 🎶.'' Ero ọpọlọpọ awọn ololufẹ Naira Marley lo jọra wọn lori ọrọ naa, n ṣe ni awọn naa fi orin ''Se bi omo jesu niwo, gbese ko Tesumole 🎶'' bọ ẹnu ni idahun wọn si esi Naira Marley. Amọ, ero awọn kan ṣọtọọtọ lori ọrọ naa, fun apẹrẹ, @funshi ni oniyẹyẹ ni pasitọ Omashola, o ni pasitọ naa ko riran pe Fashola Azeez lẹmi Eṣu. Ẹlomiran, @mubaraq_a tun kin ọrọ @funshi lẹyin, o ni Naira Marley nikan ni Ọlọrun fihan ojiṣẹ Ọlọrun naa. Epe rabandẹ lawọn kan tiẹ n fi ranṣẹ si pasitọ Omashola, wọn ni ko mọ ohun to n sọ. Laipẹ yii ni Pasitọ Omashola sọrọ loju opo Twitter rẹ, nibi ti o ti kọ orukọ awọn eeyan to ro pe wọn ko le wọ ijọba ọrun ninu eyi ti Naira Marley wa loke tente. Pasitọ Omoshola fikun ọrọ rẹ pe Naira Marley ni lati ronu piwada ni kiakia ko too pẹ fun un. O ni awọn orin ti Naira Marley n kọ ni imisi Eṣu ninu, eyi to le ṣakoba fun ọjọ iwaju ati ayanmọ awọn ọdọ ni Naijira. Bakan naa ni ojiṣẹ Ọlọrun Omoshola kilọ fawọn ọdọ wi pe, ki wọn ye pe ara wọn ni ''Marlians.''
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51024954
5sports
UCL results: Wo ìdí tí ó fi rọrùn fún Chelsea láti bu ìfọ́jú lu Manchester City lẹ́ẹ̀mẹẹ̀ta léra wọn
Yoruba bọ, wọn ni paa lẹẹkinni, paa lẹẹkeji, paa lẹẹkẹta. Bi oju ọhun ko ba fọ, yoo di bai bai. Bayii ni Chelsea ṣe dijgbaju olooyi ru Manchester City nini ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba UEFA Champions to waye lalẹ ọjọ Abamẹta ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun ọdun 2021. Ninu idije Premier League ni Chelsea ti kọkọ fagba han Man City lẹyin ti Thomas Tuchel di akọnimọọgba Chelsea. Kẹrẹ kẹrẹ, Man City ati Chelsea tun pade nini ipele to kangun si aṣekagba idije FA Cup, iya naa lo tun bade fun Man City lọwọ Chelsea. Ọpọ lo ti ro pe ina eṣi ko le jo Man City nigba mẹta lere wọn, amọ ina yii jo wọn raurau nio. Aṣeju Pep Guardiola ṣakoba fun Manchester City Ọpọ onimọ nipa ere bọọlu ni wọn ti di ẹbi ru olukọni Man City, Pep Guardiola fun aṣeju nipa bi o ṣe maa n to awọn agbabọọlu to maa n lo fun awọn ifẹsẹwọnsẹ to lamilaaka. Iru iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ fun igba meji ninu idije Champions League nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Lyon ati Monaco lo City jade ninu idije naa lai ro tẹlẹ. Ohun to ya gbogbo eeyan lẹnu to fi mọ olukọni Chelsea fun ra rẹ, Tuchel ni pe Guardiola ko fi agbaọjẹ agbabọọlu arin gbungbun rẹ Fernandinho sara awọn to bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba Champions League ọjọ Abamẹta. Ohun to tumọ si nipe ko si agbabọọlu to le di aarin mu fun City ni wọn igba ti o jẹ pe Rodri tabi Fernandinho ko si nibẹ. Eyi lo ṣakoba fun City nitori ti wọn ba ti lọ siwaju bayii ni Chelsea ri ọna lọ si ile wọn lati ṣe wọn ni suta. Apa keji ere bọọlu naa ni Guardiola gbe Fernadinho wọle, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.
UCL results: Wo ìdí tí ó fi rọrùn fún Chelsea láti bu ìfọ́jú lu Manchester City lẹ́ẹ̀mẹẹ̀ta léra wọn Yoruba bọ, wọn ni paa lẹẹkinni, paa lẹẹkeji, paa lẹẹkẹta. Bi oju ọhun ko ba fọ, yoo di bai bai. Bayii ni Chelsea ṣe dijgbaju olooyi ru Manchester City nini ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba UEFA Champions to waye lalẹ ọjọ Abamẹta ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun ọdun 2021. Ninu idije Premier League ni Chelsea ti kọkọ fagba han Man City lẹyin ti Thomas Tuchel di akọnimọọgba Chelsea. Kẹrẹ kẹrẹ, Man City ati Chelsea tun pade nini ipele to kangun si aṣekagba idije FA Cup, iya naa lo tun bade fun Man City lọwọ Chelsea. Ọpọ lo ti ro pe ina eṣi ko le jo Man City nigba mẹta lere wọn, amọ ina yii jo wọn raurau nio. Aṣeju Pep Guardiola ṣakoba fun Manchester City Ọpọ onimọ nipa ere bọọlu ni wọn ti di ẹbi ru olukọni Man City, Pep Guardiola fun aṣeju nipa bi o ṣe maa n to awọn agbabọọlu to maa n lo fun awọn ifẹsẹwọnsẹ to lamilaaka. Iru iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ fun igba meji ninu idije Champions League nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Lyon ati Monaco lo City jade ninu idije naa lai ro tẹlẹ. Ohun to ya gbogbo eeyan lẹnu to fi mọ olukọni Chelsea fun ra rẹ, Tuchel ni pe Guardiola ko fi agbaọjẹ agbabọọlu arin gbungbun rẹ Fernandinho sara awọn to bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba Champions League ọjọ Abamẹta. Ohun to tumọ si nipe ko si agbabọọlu to le di aarin mu fun City ni wọn igba ti o jẹ pe Rodri tabi Fernandinho ko si nibẹ. Eyi lo ṣakoba fun City nitori ti wọn ba ti lọ siwaju bayii ni Chelsea ri ọna lọ si ile wọn lati ṣe wọn ni suta. Apa keji ere bọọlu naa ni Guardiola gbe Fernadinho wọle, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-57297671
2health
Àwọn dókítà ṣe ìpínyà ìbejì tí orí wọn lẹ̀pọ̀ láti orílẹ̀-èdè méjì ọ̀tọ̀tọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rọ Virtual Reality
Awọn dokita lorilẹ-ede Brazil to ṣe ipinya awọn ibeji ti wọn lẹpọ lati ori pẹlu imọ ẹrọ Virtual Reality, VR. Wọn ṣe iṣẹ abẹ naa fun awọn ọmọde ọhun ti wọn jẹ ọmọ ọdun mẹta, Bernardo ati Arthur Lima nile iwosan kan niluu Rio de Janeiro pẹlu itọsọna lati ile iwosan miran,  Great Ormond Street Hospital, to wa niluu London. Ikọ to ṣiṣẹ abẹ naa lo ọpọlọpọ oṣu lati kẹkọọ nipa bi wọn yoo ṣe ṣiṣẹ abẹ ọhun lẹyin ti wọn ti kọkọ ya aworan awọn ọmọ naa pẹlu ẹrọ CT ati MRI. Ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba ti wọn ṣe onigbọwọ bi wọn ṣe pin awọn ọmọ ọhun, Gemini Untwined, ni ipinya naa jẹ eyii to lagbara ju ti awọn tii ṣe. Adari ajọ naa, ọgbẹni Jeelani sọ pe o jẹ igba akọkọ ti awọn dokita yoo wa ni orilẹ-ede ọtọtọ ti wọn yoo si ṣiṣẹ abẹ ninu yara kan naa lori ẹrọ Virtual Reality. Igba meje ọtọtọ lawọn ibeji naa ṣiṣẹ abẹ eyii ti ko din ni wakati mẹtadinlọgbọn, nnkan bii ọgọrun oṣiṣẹ lo si wa nibẹ nigba ti wọn n ṣẹ eyii to kẹyin. Nigba ti yoo sọrọ lori bi iṣẹ abẹ naa ṣe waye lori ẹrọ VR, ọgbẹni Jeelani sọ fun ileeṣẹ iroyin PA pe “Ohun iyalẹnu ni iṣẹ abẹ naa jẹ, ara meeriri ni pe a le maa wo ohun ti yoo ṣẹlẹ ki a si le ṣiṣẹ abẹ naa lori kọmputa ko to di pe a fi awọn ọmọ naa sinu ewu kankan.” “Awọn eeyan kan gbabọ pe irufẹ iṣẹ abẹ bayii lo lewu julọ ninu iran tiwa yii amọ bi a ṣe ṣiṣe abẹ naa lori Virtual Relaity dabi igba ti eeyan ba lọ sinu aye miran lori Mars ni.” Ni bayii, awọn ibeji naa ti wa  nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju lẹyin iṣẹ abẹ ọhun. Awọn dokita sọ pe oṣu mẹfa gbako ni wọn yoo lo nile iwasan naa lẹyin iṣẹ abẹn ọhun ki ara wọn le mokun daadaa. Ẹwẹ, ajọ Gemini Untwined sọ pe ẹyọkan ninu ẹgbẹrun lọna ọgọta ibeji lagbaye ni wọn maa n lẹpọ lati ori.
Àwọn dókítà ṣe ìpínyà ìbejì tí orí wọn lẹ̀pọ̀ láti orílẹ̀-èdè méjì ọ̀tọ̀tọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rọ Virtual Reality Awọn dokita lorilẹ-ede Brazil to ṣe ipinya awọn ibeji ti wọn lẹpọ lati ori pẹlu imọ ẹrọ Virtual Reality, VR. Wọn ṣe iṣẹ abẹ naa fun awọn ọmọde ọhun ti wọn jẹ ọmọ ọdun mẹta, Bernardo ati Arthur Lima nile iwosan kan niluu Rio de Janeiro pẹlu itọsọna lati ile iwosan miran,  Great Ormond Street Hospital, to wa niluu London. Ikọ to ṣiṣẹ abẹ naa lo ọpọlọpọ oṣu lati kẹkọọ nipa bi wọn yoo ṣe ṣiṣẹ abẹ ọhun lẹyin ti wọn ti kọkọ ya aworan awọn ọmọ naa pẹlu ẹrọ CT ati MRI. Ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba ti wọn ṣe onigbọwọ bi wọn ṣe pin awọn ọmọ ọhun, Gemini Untwined, ni ipinya naa jẹ eyii to lagbara ju ti awọn tii ṣe. Adari ajọ naa, ọgbẹni Jeelani sọ pe o jẹ igba akọkọ ti awọn dokita yoo wa ni orilẹ-ede ọtọtọ ti wọn yoo si ṣiṣẹ abẹ ninu yara kan naa lori ẹrọ Virtual Reality. Igba meje ọtọtọ lawọn ibeji naa ṣiṣẹ abẹ eyii ti ko din ni wakati mẹtadinlọgbọn, nnkan bii ọgọrun oṣiṣẹ lo si wa nibẹ nigba ti wọn n ṣẹ eyii to kẹyin. Nigba ti yoo sọrọ lori bi iṣẹ abẹ naa ṣe waye lori ẹrọ VR, ọgbẹni Jeelani sọ fun ileeṣẹ iroyin PA pe “Ohun iyalẹnu ni iṣẹ abẹ naa jẹ, ara meeriri ni pe a le maa wo ohun ti yoo ṣẹlẹ ki a si le ṣiṣẹ abẹ naa lori kọmputa ko to di pe a fi awọn ọmọ naa sinu ewu kankan.” “Awọn eeyan kan gbabọ pe irufẹ iṣẹ abẹ bayii lo lewu julọ ninu iran tiwa yii amọ bi a ṣe ṣiṣe abẹ naa lori Virtual Relaity dabi igba ti eeyan ba lọ sinu aye miran lori Mars ni.” Ni bayii, awọn ibeji naa ti wa  nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju lẹyin iṣẹ abẹ ọhun. Awọn dokita sọ pe oṣu mẹfa gbako ni wọn yoo lo nile iwasan naa lẹyin iṣẹ abẹn ọhun ki ara wọn le mokun daadaa. Ẹwẹ, ajọ Gemini Untwined sọ pe ẹyọkan ninu ẹgbẹrun lọna ọgọta ibeji lagbaye ni wọn maa n lẹpọ lati ori.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/ckky6dpxkn7o
2health
Femi Fani-Kayode: Iléèwòsàn Kubwa l'Abuja wú ẹ̀rí sítà tó fihàǹ pé FFK parọ́
Awọn alasẹ ile iwosan ijọba to wa ni agbegbe Kubwa niluu Abuja ti ni awọn kò gba Minisita irina ofurufu tẹ́lẹ̀ rí, Femi Fani-Kayode gẹgẹ bi alaarẹ nileewosan awọn. Oludari ẹ̀ka àkọsílẹ̀ eto ìlera nileewosan náà, Bassey Amah fi èyí lédè fún Adajọ agba Olubunmi ti ilé ẹjọ́ to n gbọ́ ẹjọ́ àkànṣe ni Ikeja nipinle Eko pe Kayode kii ṣe aláìsàn ọdọ awọn kò si ni àkọsílẹ̀ itọju lọdọ àwọn. Femi Fani-Kayode ń jẹjọ lọwọ lórí ẹ̀sùn mejila to ni ṣe pẹlu lilo iwe yíyí gẹgẹ bii ìwé ẹ̀rí ìlera àtàwọn ìwé míì tí wọn yí. Judasi ìran Oduduwa ni Femi Fani-Kayode pẹ̀lú bó ṣe darapọ̀ mọ́ APC- Sheikh Gumi Ojú ayé lásán ni Buhari ń ṣe, kò ní ifẹ́ ọmọ Nàìjíríà lọ́kàn - Fani-Kayode Ipò àgbà ló yẹ́ kí a ti bá olórí - Fani-Kayode Femi Fani-Kayode ṣàlàyé bí ìrìnàjò rẹ̀ sọ́dọ̀ EFCC ṣe jẹ́ Àjọ to n rí si ìwà jẹgudujẹra, EFCC tí kanlẹ fi ẹ̀sùn kan an pé ó lo Dokita kan, Ogieva Oziegbe láti kọ ayédèrú ìwé ẹ̀rí ìlera fún un èyí ti ìròyìn ni ó fihan níwájú Adajọ Daniel Osiagor to n dájọ́ rẹ lórí ẹ̀sùn ṣíṣe owó ìlú basubasu amọ tí Fani-Kayode ni òun kò jẹbi ẹ̀sùn náà. Nigbati tí ìgbẹ́jọ náà yoo fi tesiwaju ni Ọjọbọ, o hande pe dókítà to buwọlu ìwé ẹ̀rí náà kii ṣe oṣiṣẹ ileewosan Kubwa. Àwọn aláṣẹ ileewosan náà nígbà tí ìwádìí wọn jáde, ó fihan pe awọn kan yí ìwé náà ni. Wo ohun tí Jaruma Oníṣòwò “Kayamata” tún ṣe tí wọ́n ń gbé e padà lọ s'ẹ́wọ̀n Ìdí tí ìyàwó Ààrẹ, Aisha Buhari fi lọ ìpàdé awọn aṣòfin Pásítọ̀ tó pe omidan fún ìtúsílẹ̀ ọkọ ọrun fipá ba lòpọ̀ l‘Ogun Nígbà náà ni Adajọ dá ẹjọ́ náà láti gbé àjọ EFCC lẹyin to sì ni lóòtọ́ bo tilẹ̀ jẹ pe ileewosan Kubwa náà ni ìwé ẹ̀rí yìí tí jáde wá, wọn kò ní aridaju ayafi ti olodani kan ba ṣi aṣọ lójú ẹ atipe Ẹlẹ́rìí tí wọn pé gẹ́gẹ́ bíi asoju ileewosan ohun ni nomba to wà lórí ìwé náà kò tilẹ̀ ki n se tí ileewosan awọn rárá. Adajọ tí sún ẹjọ́ náà síwájú di ọjọ karundinlogbon oṣù Kejì ọdún 2022.
Femi Fani-Kayode: Iléèwòsàn Kubwa l'Abuja wú ẹ̀rí sítà tó fihàǹ pé FFK parọ́ Awọn alasẹ ile iwosan ijọba to wa ni agbegbe Kubwa niluu Abuja ti ni awọn kò gba Minisita irina ofurufu tẹ́lẹ̀ rí, Femi Fani-Kayode gẹgẹ bi alaarẹ nileewosan awọn. Oludari ẹ̀ka àkọsílẹ̀ eto ìlera nileewosan náà, Bassey Amah fi èyí lédè fún Adajọ agba Olubunmi ti ilé ẹjọ́ to n gbọ́ ẹjọ́ àkànṣe ni Ikeja nipinle Eko pe Kayode kii ṣe aláìsàn ọdọ awọn kò si ni àkọsílẹ̀ itọju lọdọ àwọn. Femi Fani-Kayode ń jẹjọ lọwọ lórí ẹ̀sùn mejila to ni ṣe pẹlu lilo iwe yíyí gẹgẹ bii ìwé ẹ̀rí ìlera àtàwọn ìwé míì tí wọn yí. Judasi ìran Oduduwa ni Femi Fani-Kayode pẹ̀lú bó ṣe darapọ̀ mọ́ APC- Sheikh Gumi Ojú ayé lásán ni Buhari ń ṣe, kò ní ifẹ́ ọmọ Nàìjíríà lọ́kàn - Fani-Kayode Ipò àgbà ló yẹ́ kí a ti bá olórí - Fani-Kayode Femi Fani-Kayode ṣàlàyé bí ìrìnàjò rẹ̀ sọ́dọ̀ EFCC ṣe jẹ́ Àjọ to n rí si ìwà jẹgudujẹra, EFCC tí kanlẹ fi ẹ̀sùn kan an pé ó lo Dokita kan, Ogieva Oziegbe láti kọ ayédèrú ìwé ẹ̀rí ìlera fún un èyí ti ìròyìn ni ó fihan níwájú Adajọ Daniel Osiagor to n dájọ́ rẹ lórí ẹ̀sùn ṣíṣe owó ìlú basubasu amọ tí Fani-Kayode ni òun kò jẹbi ẹ̀sùn náà. Nigbati tí ìgbẹ́jọ náà yoo fi tesiwaju ni Ọjọbọ, o hande pe dókítà to buwọlu ìwé ẹ̀rí náà kii ṣe oṣiṣẹ ileewosan Kubwa. Àwọn aláṣẹ ileewosan náà nígbà tí ìwádìí wọn jáde, ó fihan pe awọn kan yí ìwé náà ni. Wo ohun tí Jaruma Oníṣòwò “Kayamata” tún ṣe tí wọ́n ń gbé e padà lọ s'ẹ́wọ̀n Ìdí tí ìyàwó Ààrẹ, Aisha Buhari fi lọ ìpàdé awọn aṣòfin Pásítọ̀ tó pe omidan fún ìtúsílẹ̀ ọkọ ọrun fipá ba lòpọ̀ l‘Ogun Nígbà náà ni Adajọ dá ẹjọ́ náà láti gbé àjọ EFCC lẹyin to sì ni lóòtọ́ bo tilẹ̀ jẹ pe ileewosan Kubwa náà ni ìwé ẹ̀rí yìí tí jáde wá, wọn kò ní aridaju ayafi ti olodani kan ba ṣi aṣọ lójú ẹ atipe Ẹlẹ́rìí tí wọn pé gẹ́gẹ́ bíi asoju ileewosan ohun ni nomba to wà lórí ìwé náà kò tilẹ̀ ki n se tí ileewosan awọn rárá. Adajọ tí sún ẹjọ́ náà síwájú di ọjọ karundinlogbon oṣù Kejì ọdún 2022.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60501035
1entertainment
Grace Oyin Adejobi: Bí mo bá tún ayé wá, ọkọ mi ni màá padà fẹ́
Gbajumọ ni mama Grace Owoola Oyin-Adejobi ti ọpọ eeyan mọ si Iya Osogbo nitori o wa lara awọn obinrin to bẹrẹ ere tiata nibẹrẹ pẹpẹ. Iya Osogbo, ẹni to sẹsẹ se ọjọ ibi ọdun kejilelaadọrun laipẹ yii ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn iriri rẹ nile aye, ajọsepọ pẹlu ọkọ rẹ ati ere tiata. O fikun pe iyawo marun ni oun fẹ fun ọkọ oun lati mu ki agbo ere tiata rẹ se aseye, ti oun ko si kabamọ nipa igbesẹ naa. Grace Oyin Adejobi, ti ọkọ rẹ, Oyin Adejobi naa jẹ gbajumọ osere tiata tun fikun pe ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni oun ati ọkọ oun ti pade, ti aanu rẹ si maa n se oun tori ipo akanda ẹda to wa. Nigba to n salaye idi ti ko fi tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ lati kawe de ibi to lapẹrẹ, Iya Osogbo nigba ti oun wa niwe kẹrin ni oun fi owo ile ẹkọ ra asọ ọdun Ileya. O ni idi ree ti wọn ko fi jẹ ki oun kawe siwaju mọ.
Grace Oyin Adejobi: Bí mo bá tún ayé wá, ọkọ mi ni màá padà fẹ́ Gbajumọ ni mama Grace Owoola Oyin-Adejobi ti ọpọ eeyan mọ si Iya Osogbo nitori o wa lara awọn obinrin to bẹrẹ ere tiata nibẹrẹ pẹpẹ. Iya Osogbo, ẹni to sẹsẹ se ọjọ ibi ọdun kejilelaadọrun laipẹ yii ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn iriri rẹ nile aye, ajọsepọ pẹlu ọkọ rẹ ati ere tiata. O fikun pe iyawo marun ni oun fẹ fun ọkọ oun lati mu ki agbo ere tiata rẹ se aseye, ti oun ko si kabamọ nipa igbesẹ naa. Grace Oyin Adejobi, ti ọkọ rẹ, Oyin Adejobi naa jẹ gbajumọ osere tiata tun fikun pe ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni oun ati ọkọ oun ti pade, ti aanu rẹ si maa n se oun tori ipo akanda ẹda to wa. Nigba to n salaye idi ti ko fi tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ lati kawe de ibi to lapẹrẹ, Iya Osogbo nigba ti oun wa niwe kẹrin ni oun fi owo ile ẹkọ ra asọ ọdun Ileya. O ni idi ree ti wọn ko fi jẹ ki oun kawe siwaju mọ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58389141
1entertainment
Tope Alabi, ìyá mi ló jẹ́..., àmọ́ mo fẹ́ ... - Yinka Alaseyori
Iroyin to n jade lọwọlọwọ ni pe olorin ẹmi to ti di ilumọka bayii laarin ọjọ mẹta pere, Yinka Alaseyori ti sọrọ soke si bi ogbontarigi olorin Tope Alabi ṣe sọrọ ni gbangba pe ko tọ ki o pe Ọlọrun ni "Oniduro Mi". O ti fi ọrọ ranṣẹ si Tope Alabi ati gbogbo eeyan. Adeyinka Alaseyori kọkọ ṣebi ẹni ti ko fẹ mẹnu ba ọrọ yii rara lati igba to ti ṣẹlẹ gẹgẹ bi ko ṣe ba ile iṣẹ́ iroyin kankan sọrọ lati ọjọ yii ti pada fọhun. Nibi ti Yinka Alaseyori ti n ṣe isin orin iyin lati ṣaami ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lo ti bẹ gbogbo awọn eeyan lori ọrọ yii. Lo ba tun fi adura bọ ẹnu fun gbogbo awọn to n ṣe iṣẹ to jẹ ọna to tọ pe: "gbogbo ẹyin tẹ n ṣe iṣẹ ọna to tọ to n mu ounjẹ wa sori tabili yin, ẹ o maa lowo sii ni". Àjinigbé pa ọmọ méjì wọ́n ji méjì gbé lọ tí wan jẹ́ ọmọ òbí kan ni Ondo, Kí ló fa ikú akẹ́kọ̀ọ́ ẹni ọdún 23 yìí tí ọlópàá ba oku rẹ̀ nílé ìtura? Alaseyori kọ́ ló ni orin "Oniduro Mi", àmọ́ ìdí tí mi ò ṣe bá a jà pé ó jí orin mi kọ nìyìí - Tolu Adelegan Ìjọba Saudi dájọ́ ikú fún ọ̀dọ́ kan lórí ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ láti kékéré, ìdí rèé Nǹkan tí a mọ̀ nípa ìlera Asiwaju Ahmed Tinubu Ayédèrú òṣìṣẹ́ ìjọba ni Baba Ijesha fà kalẹ́ ló jẹ́ kó ṣì wà láhámọ́ - Ọlọ́pàá Alaṣeyori ni ti oun ba ti ṣe tan nibi eto orin iyin naa, ounjẹ loun n lọ jẹ gẹgẹ bo ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to jẹ ọjọ kẹrin oṣu kẹfa gangan amọ to ni ko saye lati ṣe ayẹyẹ afi titi di oni ti oun fi ṣe eto orin iyin. Lẹyin ọpọlọpọ wakati orin iyin ti akọroyin BBC Yoruba joko ti loju opo ayelujara Adeyinka Alaṣeyori funrarẹ, ti oun ati olorin ẹmi mii Dare Melody kọ lati fi ṣide eto naa, Alaseyori fẹ re si orin alujo tori o ni "mo fẹ ki ẹ jo amọ mo fẹ fi Ọlọrun bẹ yin..." Alaseyori ni "mo kọkọ fẹ dupẹ lọwọ gbogbo eeyan kaakiri agbaye, loke okun ati nile nibi fun ifẹ yin. "Mummy Tope Alabi, iyaa mi ni". O tẹsiwaju pe: "Iya ni Tope Alabi jẹ si mi, ọna kan tabi omiran si ni gbogbo wa ti jẹ anfani lara awọn orin rẹ... Ẹ jọwọ ẹ jẹ ki alafia jọba". Alaseyori ti ijo ati ohun orin didun si ba nile tẹlẹ ti gbogbo ijo wa lara rẹ - lo ba ni kan si orin ati ijo si Ọlọrun ati fun awọn ololufẹ rẹ. Yinka Alaseyori ko mẹnu ba idi kankan ti ko fi yẹ ki o kọ orin naa gẹgẹ igun awọn eeyan kan ṣe n ja fun pe kii ṣe ohun gangan ni Ọlọrun fun ni orin naa lati kọ kalẹ. Iroyin ti a kojọ ati ifọrọwanilẹnuwo BBC Yoruba pẹlu ni ti o gba imisi orin naa gangan, Evangelist Toluwalase Aladelegan fihan pe ọdun 2014 ni Tolu gba imisi orin naa to si tun kọ jade ni ile ito orin pọ. Mo rí òkú TB Joshua tó yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ - Jaiye Kuti Wòlíì Genesis fèsì lórí ọ̀rọ̀ Tope Alabi nípa orin 'Oniduromi' Ẹwẹ, Alaṣeyori to jẹ́ olorin ẹmi to maa n kọ gbogbo orin yala tirẹ ni tabi ti ẹlomiran bi o ba ṣe ni idari kẹnu bọ awọn orin to wu awọn eeyan lori gan. Diẹ lara wọn niyii: Iṣẹ nla lẹ ṣe laye mi Ẹyin tẹ fun wa lowo tẹ́ẹ fun wa laṣọ, fun wa ni ipara, ẹ o maa lowo, lọla sii. Ọlọrun ko da bi eniyan, eeniyan aronipin... Iwo ko lo da mi, iwọ kọ lo bi mi, o si n sọrọ bi Eledumare Jesus na you big o, Ọga patapata... Ẹ ṣee aye ọpẹ yọ, mo dupẹ aye ọpẹ pada yọ N o la agbaye ja, n go si ri bi Ọba... Oniduro Mi ẹ ṣeun o...
Tope Alabi, ìyá mi ló jẹ́..., àmọ́ mo fẹ́ ... - Yinka Alaseyori Iroyin to n jade lọwọlọwọ ni pe olorin ẹmi to ti di ilumọka bayii laarin ọjọ mẹta pere, Yinka Alaseyori ti sọrọ soke si bi ogbontarigi olorin Tope Alabi ṣe sọrọ ni gbangba pe ko tọ ki o pe Ọlọrun ni "Oniduro Mi". O ti fi ọrọ ranṣẹ si Tope Alabi ati gbogbo eeyan. Adeyinka Alaseyori kọkọ ṣebi ẹni ti ko fẹ mẹnu ba ọrọ yii rara lati igba to ti ṣẹlẹ gẹgẹ bi ko ṣe ba ile iṣẹ́ iroyin kankan sọrọ lati ọjọ yii ti pada fọhun. Nibi ti Yinka Alaseyori ti n ṣe isin orin iyin lati ṣaami ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lo ti bẹ gbogbo awọn eeyan lori ọrọ yii. Lo ba tun fi adura bọ ẹnu fun gbogbo awọn to n ṣe iṣẹ to jẹ ọna to tọ pe: "gbogbo ẹyin tẹ n ṣe iṣẹ ọna to tọ to n mu ounjẹ wa sori tabili yin, ẹ o maa lowo sii ni". Àjinigbé pa ọmọ méjì wọ́n ji méjì gbé lọ tí wan jẹ́ ọmọ òbí kan ni Ondo, Kí ló fa ikú akẹ́kọ̀ọ́ ẹni ọdún 23 yìí tí ọlópàá ba oku rẹ̀ nílé ìtura? Alaseyori kọ́ ló ni orin "Oniduro Mi", àmọ́ ìdí tí mi ò ṣe bá a jà pé ó jí orin mi kọ nìyìí - Tolu Adelegan Ìjọba Saudi dájọ́ ikú fún ọ̀dọ́ kan lórí ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ láti kékéré, ìdí rèé Nǹkan tí a mọ̀ nípa ìlera Asiwaju Ahmed Tinubu Ayédèrú òṣìṣẹ́ ìjọba ni Baba Ijesha fà kalẹ́ ló jẹ́ kó ṣì wà láhámọ́ - Ọlọ́pàá Alaṣeyori ni ti oun ba ti ṣe tan nibi eto orin iyin naa, ounjẹ loun n lọ jẹ gẹgẹ bo ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to jẹ ọjọ kẹrin oṣu kẹfa gangan amọ to ni ko saye lati ṣe ayẹyẹ afi titi di oni ti oun fi ṣe eto orin iyin. Lẹyin ọpọlọpọ wakati orin iyin ti akọroyin BBC Yoruba joko ti loju opo ayelujara Adeyinka Alaṣeyori funrarẹ, ti oun ati olorin ẹmi mii Dare Melody kọ lati fi ṣide eto naa, Alaseyori fẹ re si orin alujo tori o ni "mo fẹ ki ẹ jo amọ mo fẹ fi Ọlọrun bẹ yin..." Alaseyori ni "mo kọkọ fẹ dupẹ lọwọ gbogbo eeyan kaakiri agbaye, loke okun ati nile nibi fun ifẹ yin. "Mummy Tope Alabi, iyaa mi ni". O tẹsiwaju pe: "Iya ni Tope Alabi jẹ si mi, ọna kan tabi omiran si ni gbogbo wa ti jẹ anfani lara awọn orin rẹ... Ẹ jọwọ ẹ jẹ ki alafia jọba". Alaseyori ti ijo ati ohun orin didun si ba nile tẹlẹ ti gbogbo ijo wa lara rẹ - lo ba ni kan si orin ati ijo si Ọlọrun ati fun awọn ololufẹ rẹ. Yinka Alaseyori ko mẹnu ba idi kankan ti ko fi yẹ ki o kọ orin naa gẹgẹ igun awọn eeyan kan ṣe n ja fun pe kii ṣe ohun gangan ni Ọlọrun fun ni orin naa lati kọ kalẹ. Iroyin ti a kojọ ati ifọrọwanilẹnuwo BBC Yoruba pẹlu ni ti o gba imisi orin naa gangan, Evangelist Toluwalase Aladelegan fihan pe ọdun 2014 ni Tolu gba imisi orin naa to si tun kọ jade ni ile ito orin pọ. Mo rí òkú TB Joshua tó yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ - Jaiye Kuti Wòlíì Genesis fèsì lórí ọ̀rọ̀ Tope Alabi nípa orin 'Oniduromi' Ẹwẹ, Alaṣeyori to jẹ́ olorin ẹmi to maa n kọ gbogbo orin yala tirẹ ni tabi ti ẹlomiran bi o ba ṣe ni idari kẹnu bọ awọn orin to wu awọn eeyan lori gan. Diẹ lara wọn niyii: Iṣẹ nla lẹ ṣe laye mi Ẹyin tẹ fun wa lowo tẹ́ẹ fun wa laṣọ, fun wa ni ipara, ẹ o maa lowo, lọla sii. Ọlọrun ko da bi eniyan, eeniyan aronipin... Iwo ko lo da mi, iwọ kọ lo bi mi, o si n sọrọ bi Eledumare Jesus na you big o, Ọga patapata... Ẹ ṣee aye ọpẹ yọ, mo dupẹ aye ọpẹ pada yọ N o la agbaye ja, n go si ri bi Ọba... Oniduro Mi ẹ ṣeun o...
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57492139
3politics
Buhari lifts Twitter ban: Buhari fún ọmọ Naijiria lẹ́bùn ayẹyẹ òmìnira, ó gbẹ́sẹ̀ kúró lórí Twitter pẹ̀lú ìkìlọ̀
Bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n ṣe ayẹyẹ ayajọ ominira ọdunkọkanlelọgọta ti orilẹede Naijiria gba ominira, Aarẹ Muhammadu Buhari ti gbẹsẹ kuro lori ofin to fi de Twitter. Ni oṣu kẹfa ọdun 2021 yii ni ijọba kede pe oun ti fofin de lilo oju opo igbọrọkaye Twitter lori ohun ti ijọba pe ni aṣilo rẹ. Buhari ni lootọọ ni Twitter wulo lati maa fi pin iroyin ni waranṣesa, ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijiria lo n lo lati huwa ọdaran. Aarẹ Buhari ni ọpọ eeyan lo n Twitter lati gbe ayederu iroyin kiri nigba ti awọn mii n loo lati da ija ẹlẹyamẹya ati ija ẹsin silẹ. ''Ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ọmọ Naijiria ni Twitter ti fun lanfani lati ba oriṣiiriṣii eeyan pade, ṣe owo ati anfani si iroyin yajo yajo. Amọ, awọn iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni Naijiria ti fihan pe awọn nkan n lo Twitter lati huwa ibajẹ lawujọ. Eyi gan an lo jẹ ki ijọba gbẹsẹ le Twitter ni ọjọ karun un oṣu karun un ọdun 2021 ki ijọba le wa ojutuu si iṣoro to n koju Naijiria nipasẹ Twitter. Mo ṣe agbekalẹ igbimọ to ba Twitter sọrọ lati jiroro lori ọna abayọ eleyii ti wọn jọ fẹnu ko lori rẹ.
Buhari lifts Twitter ban: Buhari fún ọmọ Naijiria lẹ́bùn ayẹyẹ òmìnira, ó gbẹ́sẹ̀ kúró lórí Twitter pẹ̀lú ìkìlọ̀ Bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n ṣe ayẹyẹ ayajọ ominira ọdunkọkanlelọgọta ti orilẹede Naijiria gba ominira, Aarẹ Muhammadu Buhari ti gbẹsẹ kuro lori ofin to fi de Twitter. Ni oṣu kẹfa ọdun 2021 yii ni ijọba kede pe oun ti fofin de lilo oju opo igbọrọkaye Twitter lori ohun ti ijọba pe ni aṣilo rẹ. Buhari ni lootọọ ni Twitter wulo lati maa fi pin iroyin ni waranṣesa, ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijiria lo n lo lati huwa ọdaran. Aarẹ Buhari ni ọpọ eeyan lo n Twitter lati gbe ayederu iroyin kiri nigba ti awọn mii n loo lati da ija ẹlẹyamẹya ati ija ẹsin silẹ. ''Ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ọmọ Naijiria ni Twitter ti fun lanfani lati ba oriṣiiriṣii eeyan pade, ṣe owo ati anfani si iroyin yajo yajo. Amọ, awọn iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni Naijiria ti fihan pe awọn nkan n lo Twitter lati huwa ibajẹ lawujọ. Eyi gan an lo jẹ ki ijọba gbẹsẹ le Twitter ni ọjọ karun un oṣu karun un ọdun 2021 ki ijọba le wa ojutuu si iṣoro to n koju Naijiria nipasẹ Twitter. Mo ṣe agbekalẹ igbimọ to ba Twitter sọrọ lati jiroro lori ọna abayọ eleyii ti wọn jọ fẹnu ko lori rẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58759463
2health
World Stroke Day: Ọ̀nà méje rèé láti borí àìsàn rọpá-rọṣẹ̀ tó ń pa àwọn ènìyàn ní àgbáyé!
Ajọ eto ilẹra ni Naijiria, Nigeria Medical Association, (NMA) ti sọ wi pe o kere tan eniyan mẹtala lagbaye ni yoo ni aisan rọpa-rọṣẹ lagbaye. Alaga Ajọ NMA ni ipinlẹ Kwara, Ọjọgbọn Baba Issa ni awọn fi ikilọ naa lede lati ṣayajọ Ọjọ aisan rọpa-rọṣẹ lagbaye, World Stroke Day. NMA ni o kere tan eniyan miliọnu mẹtala ni yoo ni aisan rọpa-rọṣẹ lagbaye, ti o kere tan eniyan miliọnu marun un yoo ba arun naa lọ. O salaye pe Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Kẹwaa, ọdun 2021 ni ayajọ ọdun naa ni agbaye, to si ni ikede yii yoo mu ki awọn eniyan kiyesi aisan yii lagbaye, nitori o ti fẹ di aisan tile -toko. Bakan naa ni wọn fikun un pe aisan rọpa-rọṣẹ ni ohun pa awọn eniyan julọ ni agbaye ati awọn to ti da dubulẹ si ti le si ni ojoojumọ. Bi o ṣe le da aisan rọpa rọṣẹ mọ ti o ba n bọ; Kiakia ni ki ẹ pe ileewosan pajawiri ti o ba ri awọn ami wọn yii.
World Stroke Day: Ọ̀nà méje rèé láti borí àìsàn rọpá-rọṣẹ̀ tó ń pa àwọn ènìyàn ní àgbáyé! Ajọ eto ilẹra ni Naijiria, Nigeria Medical Association, (NMA) ti sọ wi pe o kere tan eniyan mẹtala lagbaye ni yoo ni aisan rọpa-rọṣẹ lagbaye. Alaga Ajọ NMA ni ipinlẹ Kwara, Ọjọgbọn Baba Issa ni awọn fi ikilọ naa lede lati ṣayajọ Ọjọ aisan rọpa-rọṣẹ lagbaye, World Stroke Day. NMA ni o kere tan eniyan miliọnu mẹtala ni yoo ni aisan rọpa-rọṣẹ lagbaye, ti o kere tan eniyan miliọnu marun un yoo ba arun naa lọ. O salaye pe Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Kẹwaa, ọdun 2021 ni ayajọ ọdun naa ni agbaye, to si ni ikede yii yoo mu ki awọn eniyan kiyesi aisan yii lagbaye, nitori o ti fẹ di aisan tile -toko. Bakan naa ni wọn fikun un pe aisan rọpa-rọṣẹ ni ohun pa awọn eniyan julọ ni agbaye ati awọn to ti da dubulẹ si ti le si ni ojoojumọ. Bi o ṣe le da aisan rọpa rọṣẹ mọ ti o ba n bọ; Kiakia ni ki ẹ pe ileewosan pajawiri ti o ba ri awọn ami wọn yii.
https://www.bbc.com/yoruba/media-59100635
4religion
Osun Masqurade attack: Kayode Esuleke, olórí egúngún to bá àwọn musulumi jà ní Osogbo wà láhámọ́ ọlọ́pàá
Rogbodiyan to waye laarin awọn ẹlẹsin musulumi ti ijọ Kamorudeen Society Central Mosque ati eleegun nilu Osogbo ni ọjọ Àìkú ti gba ọna miran yọ. Idi ni pe ileesẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun ti mu olori awọn eleegun naa, oloye Kayode Eṣuleke si ahamọ. Gẹgẹ bi iroyin abẹle kan ṣe sọ, ikọ ọtẹlẹmuyẹ fun ọga agba ọlọpaa, IG Intelligence response Unit, lo ranṣẹ pe oloye Esuleke si ileeṣẹ wọn nilu Osogbo fun ifọrọwanilẹnuwo nibẹ, ti wọn si ti fi si ahamọ. Lẹyin rogbodiyan to waye laarin awọn eleegun atawọn ẹlẹsin Musulumi niluu Osogbo, awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ti baba BBC Yoruba sọrọ lori ohun ti oju wọn ri. Lasiko ti BBC Yoruba ṣabẹwo si agbegbe naa, ọkan lara awọn Musulumi ọhun, Salahudeen Yusuf sọ pe adura ki Naijiria le dara ni awọn n gba lọwọ, ki awọn eleegun naa to kọlu awọn. O ni "Bi a ṣe kirun Aila tan ni awọn eleegun naa n lulu kọja, lẹyin naa ni wọn duro lagbegbe mọṣalaṣi wa." "Ka to wi ka to fọ, wọn ti bẹrẹ si n sọko si wa, ti wọn si bẹrẹ si n yinbọn si wa." "Ibọn ba baba agbalaga kan lara wa, awọn miran ti ibọn ba ṣi wa nile iwosan LAUTECH bayii nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ." Obinrin kan lara awọn Musulumi naa tun ṣalaye fun BBC pe, awọn ọlọpaa wa lara awọn elegun naa, ṣugbọn gbogbo akitiyan awọn lati rọ awọn ọlọpaa ọhun lati pana rogbodiyan naa, lo ja si pabo. O ni awọn ko mura ija, bẹẹ ni awọn ko ba awọn eeyan naa ja nitori adura lawọn n gba, ṣugbọn awọn eleegun naa lo kọlu awọn, ninu eyii ti ẹmi kan ninu wọn ti sọnu. Ẹwẹ, BBC kan si aṣoju idile awọn eleegun naa, Fasola Esuleke, to si sọ pe eegun idile wọn kii ṣe eegun oni jagidijagan. Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn elegun naa n kọja lọ lagbegbe ti Mọṣalaṣi ọhun wa ni, ki awọn Musulumi ọhun to tọ ija awọn. Fasola ni awọn kan n kọja lọ ni, kii ṣe awọn ya lọ ba awọn Musulumi naa. O ni "Igba ti a n bọ ni gbogbo wọn kọlu wa to fi mọ awọn ọmọde to wa lara awọn." "Wọn ko ada, igo ati okuta to fi mọ ibọn, koda wọn dana silẹ ti wọn si pe awọn yoo sun ẹku eegun." "Nibi ti a ti n du ki wọn ma farakan egungun, ni ọkan lara wọn gbiyanju lati ṣi ẹku egun kuro loju rẹ ṣugbọn egun ọhun salọ." Fasola tẹsiwaju pe kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn Musulumi naa ati olori wọn yoo kọlu awọn. O fi kun pe pupọ ninu awọn ni wọn ṣe leṣe, koda o ni wọn gun ọmọ kan lara wọn lọbẹ ti ifun rẹ fi tu jade. Aṣoju eleegun naa pari ọrọ rẹ pe awọn ko gbọ pe ẹnikẹni jade laye lasiko rogbodiyan naa. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola ṣalaye fun BBC pe wọn ti fi ọrọ naa to awọn leto, lootọ si ni ikọlu waye ṣugbọn awọn ko tii le sọ ẹni to kọkọ kọlu ara ninu igun ẹgbẹ. Opalola ṣalaye pe lootọ ni ẹnikan ba iṣẹlẹ naa lọ ṣugbọn awọn ko tii mọ irufẹ ẹni ti ẹni naa jẹ, nitori awọn mọlẹbi rẹ ko tii wa sọdọ awọn. O fi kun pe awọn ti fi ṣikun ofin mu awọn eeyan kan, ṣugbọn o ni oun ko tii le sọ ni pato iye eeyan ti awọn ti mu. Opalola pari ọrọ rẹ pe kii ṣe awọn Fulani lo wa nidi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn iwadii ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun. Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin? Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe rogbodiyan kan bẹ silẹ nilu Osogbo lọjọ Aiku ana eyi ta gbọ pe o mu ẹmi eeyan kan lọ nigba ti ọpọ eeyan miran sese pupọ. Bi o tilẹ jẹ pe a ko tii lee fidi ohun to fa wahala yii mulẹ amọ gẹgẹ bi iwe iroyin Osun Defender ti wi, awọn egungun kan to dihamọra pẹlu ohun ija oloro lo fa sababi isẹlẹ naa. A gbọ pe awọn egungun yii lo ti kọkọ n dun mahuru-mahuru tẹlẹ pẹlu awọn janmọ Mọsalasi kan ti ijọ wọn n jẹ Kamorudeen Islamic Society. Asiko ti awọn ijọ ẹlẹsin Islam yii, to wa ladugbo Oluode Aranyin nilu Osogbo, si n se adura lọwọ ni wahala ọhun fọnna soju ni deede aago meji abọ ọsan. Se la gbọ pe awọn egungun yii, to ti kọkọ n paraaro agbegbe ti mọsalasi naa wa, ti wọn n lọ, ti wọn n bọ, ba sadede bẹrẹ si sọ okuta lu awọn to n kirun nibẹ. Osun Defender, to ba ọkan lara awọn to fara gbọgbẹ nibi isẹlẹ naa sọrọ, jabọ pe awọn egungun ọhun lo de si adugbo naa pẹlu ikọ ọlọpaa ati Amotekun. Amọ bawọn ikọ agbofinro naa se fi agbegbe ọhun silẹ, ni awọn egungun naa fa ibọn yọ, ti wọn si n yin lakọ-lakọ. Asiko ti ibọn yii si n dun, la gbọ pe ibọn ba Baba ijọ Mọsalasi naa, Moshood Salawudeen, to si jade laye loju ẹsẹ. Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ, Imaam Mọsalasi naa, Quyum Yunus ẹni to fidi isẹlẹ naa mulẹ salaye pe, awọn egungun yii lo ni awọn n seto adura fun orilẹede Naijiria tori aabo to mẹhẹ. Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ko tii sọ ohunkohun lori isẹlẹ yii amọ BBC Yoruba yoo tẹsiwaju lati tanna wadi isẹlẹ yii, ta si mu abọ rẹ wa fun yin laipẹ.
Osun Masqurade attack: Kayode Esuleke, olórí egúngún to bá àwọn musulumi jà ní Osogbo wà láhámọ́ ọlọ́pàá Rogbodiyan to waye laarin awọn ẹlẹsin musulumi ti ijọ Kamorudeen Society Central Mosque ati eleegun nilu Osogbo ni ọjọ Àìkú ti gba ọna miran yọ. Idi ni pe ileesẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun ti mu olori awọn eleegun naa, oloye Kayode Eṣuleke si ahamọ. Gẹgẹ bi iroyin abẹle kan ṣe sọ, ikọ ọtẹlẹmuyẹ fun ọga agba ọlọpaa, IG Intelligence response Unit, lo ranṣẹ pe oloye Esuleke si ileeṣẹ wọn nilu Osogbo fun ifọrọwanilẹnuwo nibẹ, ti wọn si ti fi si ahamọ. Lẹyin rogbodiyan to waye laarin awọn eleegun atawọn ẹlẹsin Musulumi niluu Osogbo, awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ti baba BBC Yoruba sọrọ lori ohun ti oju wọn ri. Lasiko ti BBC Yoruba ṣabẹwo si agbegbe naa, ọkan lara awọn Musulumi ọhun, Salahudeen Yusuf sọ pe adura ki Naijiria le dara ni awọn n gba lọwọ, ki awọn eleegun naa to kọlu awọn. O ni "Bi a ṣe kirun Aila tan ni awọn eleegun naa n lulu kọja, lẹyin naa ni wọn duro lagbegbe mọṣalaṣi wa." "Ka to wi ka to fọ, wọn ti bẹrẹ si n sọko si wa, ti wọn si bẹrẹ si n yinbọn si wa." "Ibọn ba baba agbalaga kan lara wa, awọn miran ti ibọn ba ṣi wa nile iwosan LAUTECH bayii nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ." Obinrin kan lara awọn Musulumi naa tun ṣalaye fun BBC pe, awọn ọlọpaa wa lara awọn elegun naa, ṣugbọn gbogbo akitiyan awọn lati rọ awọn ọlọpaa ọhun lati pana rogbodiyan naa, lo ja si pabo. O ni awọn ko mura ija, bẹẹ ni awọn ko ba awọn eeyan naa ja nitori adura lawọn n gba, ṣugbọn awọn eleegun naa lo kọlu awọn, ninu eyii ti ẹmi kan ninu wọn ti sọnu. Ẹwẹ, BBC kan si aṣoju idile awọn eleegun naa, Fasola Esuleke, to si sọ pe eegun idile wọn kii ṣe eegun oni jagidijagan. Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn elegun naa n kọja lọ lagbegbe ti Mọṣalaṣi ọhun wa ni, ki awọn Musulumi ọhun to tọ ija awọn. Fasola ni awọn kan n kọja lọ ni, kii ṣe awọn ya lọ ba awọn Musulumi naa. O ni "Igba ti a n bọ ni gbogbo wọn kọlu wa to fi mọ awọn ọmọde to wa lara awọn." "Wọn ko ada, igo ati okuta to fi mọ ibọn, koda wọn dana silẹ ti wọn si pe awọn yoo sun ẹku eegun." "Nibi ti a ti n du ki wọn ma farakan egungun, ni ọkan lara wọn gbiyanju lati ṣi ẹku egun kuro loju rẹ ṣugbọn egun ọhun salọ." Fasola tẹsiwaju pe kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn Musulumi naa ati olori wọn yoo kọlu awọn. O fi kun pe pupọ ninu awọn ni wọn ṣe leṣe, koda o ni wọn gun ọmọ kan lara wọn lọbẹ ti ifun rẹ fi tu jade. Aṣoju eleegun naa pari ọrọ rẹ pe awọn ko gbọ pe ẹnikẹni jade laye lasiko rogbodiyan naa. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola ṣalaye fun BBC pe wọn ti fi ọrọ naa to awọn leto, lootọ si ni ikọlu waye ṣugbọn awọn ko tii le sọ ẹni to kọkọ kọlu ara ninu igun ẹgbẹ. Opalola ṣalaye pe lootọ ni ẹnikan ba iṣẹlẹ naa lọ ṣugbọn awọn ko tii mọ irufẹ ẹni ti ẹni naa jẹ, nitori awọn mọlẹbi rẹ ko tii wa sọdọ awọn. O fi kun pe awọn ti fi ṣikun ofin mu awọn eeyan kan, ṣugbọn o ni oun ko tii le sọ ni pato iye eeyan ti awọn ti mu. Opalola pari ọrọ rẹ pe kii ṣe awọn Fulani lo wa nidi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn iwadii ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun. Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin? Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe rogbodiyan kan bẹ silẹ nilu Osogbo lọjọ Aiku ana eyi ta gbọ pe o mu ẹmi eeyan kan lọ nigba ti ọpọ eeyan miran sese pupọ. Bi o tilẹ jẹ pe a ko tii lee fidi ohun to fa wahala yii mulẹ amọ gẹgẹ bi iwe iroyin Osun Defender ti wi, awọn egungun kan to dihamọra pẹlu ohun ija oloro lo fa sababi isẹlẹ naa. A gbọ pe awọn egungun yii lo ti kọkọ n dun mahuru-mahuru tẹlẹ pẹlu awọn janmọ Mọsalasi kan ti ijọ wọn n jẹ Kamorudeen Islamic Society. Asiko ti awọn ijọ ẹlẹsin Islam yii, to wa ladugbo Oluode Aranyin nilu Osogbo, si n se adura lọwọ ni wahala ọhun fọnna soju ni deede aago meji abọ ọsan. Se la gbọ pe awọn egungun yii, to ti kọkọ n paraaro agbegbe ti mọsalasi naa wa, ti wọn n lọ, ti wọn n bọ, ba sadede bẹrẹ si sọ okuta lu awọn to n kirun nibẹ. Osun Defender, to ba ọkan lara awọn to fara gbọgbẹ nibi isẹlẹ naa sọrọ, jabọ pe awọn egungun ọhun lo de si adugbo naa pẹlu ikọ ọlọpaa ati Amotekun. Amọ bawọn ikọ agbofinro naa se fi agbegbe ọhun silẹ, ni awọn egungun naa fa ibọn yọ, ti wọn si n yin lakọ-lakọ. Asiko ti ibọn yii si n dun, la gbọ pe ibọn ba Baba ijọ Mọsalasi naa, Moshood Salawudeen, to si jade laye loju ẹsẹ. Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ, Imaam Mọsalasi naa, Quyum Yunus ẹni to fidi isẹlẹ naa mulẹ salaye pe, awọn egungun yii lo ni awọn n seto adura fun orilẹede Naijiria tori aabo to mẹhẹ. Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ko tii sọ ohunkohun lori isẹlẹ yii amọ BBC Yoruba yoo tẹsiwaju lati tanna wadi isẹlẹ yii, ta si mu abọ rẹ wa fun yin laipẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57634108
1entertainment
Adebimpe Oyebade and Lateef Adedimeji: Ẹlẹ́tàn ni ọkùnrin, wọn kò ṣe é gbáralé
Ggbajugbaja oṣere Nollywood, Adebimpe Oyebade, ti kegbare sita pe ẹlẹtan ni awọn ọkunrin. Nibu ọrọ kan to kọ soju opo ayelujara Instagram rẹ lo ti n beere lọwọ awọn ololufẹ rẹ pe, ki lo maa n mu ki awọn ọkunrin yi iwa wọn pada si obinrin ti wọn n fẹ, lẹyin ti ibalopọ ba ti waye laarin awọn mejeeji. O ṣalaye pe kii ṣe obinrin nikan lo ma n ṣe oju meji tabi jẹ ọdalẹ ninu irinajo ifẹ, o ni ati ọkunrin ati obinrin lo ni iwa yii lọwọ. O tọka si bi oriṣiriṣi ọkunrin ṣe ma n yi iwa pada si obinrin, ti obinrin naa ko si ni ri oju wọn nilẹ mọ, lẹyin ti ọwọ ọkunrin bẹẹ ba ti tẹ nkan to n wa ninu irinajo ifẹ naa. Ọrọ naa waye lori fidio kan to fi sita, ninu eyi ti oun ati akẹẹgbẹ rẹ, Adedimeji Lateef, ti ṣe ere kekere kan, ninu eyi ti awọn mejeeji ti jẹ ololufẹ. Ninu fidio naa, to jẹ apa kẹrin eto kan ti Adebimpe ma n ṣe, lo pe akori rẹ ni 'DiaryOfAnAfricanWoman EP 4 - MEN ARE SCUM'. Ninu fidio naa, awọn mejeeji fẹran ara wọn pupọ, ṣugbọn lẹyin asiko diẹ, Lateef ko gbe ipe Adebimpe mọ lori foonu. Ibalopọ to ti waye laarin wọn di oyun, amọ niṣe ni Lateef kọ lati gba oyun, to si sọ fun Adebimpe pe, awọn obi oun ko faramọ ki awọn fẹra gẹgẹ bi ọkọ ati iyawo. Adebimpe beere pe ,ki lo de ti awọn ọkunrin kan ma n tan obinrin, nigba ti wọn mọ pe awọn ko ni erongba lati fẹ ẹ sile? O ni ti ọkunrin ba ṣẹṣẹ n fẹ obinrin, o ma n fi aaye silẹ lati wa pẹlu rẹ, ṣugbọn to ba ti kọja lara rẹ tan, aye lati rira ko ni i si mọ. O wa sọ fun awọn ọkunrin pe, ki wọn yi iwa pada, ki wọn o ṣe obinrin bi wọn ba ṣe fẹ ki ọkunrin mii ṣe si ọmọ wọn obinrin.
Adebimpe Oyebade and Lateef Adedimeji: Ẹlẹ́tàn ni ọkùnrin, wọn kò ṣe é gbáralé Ggbajugbaja oṣere Nollywood, Adebimpe Oyebade, ti kegbare sita pe ẹlẹtan ni awọn ọkunrin. Nibu ọrọ kan to kọ soju opo ayelujara Instagram rẹ lo ti n beere lọwọ awọn ololufẹ rẹ pe, ki lo maa n mu ki awọn ọkunrin yi iwa wọn pada si obinrin ti wọn n fẹ, lẹyin ti ibalopọ ba ti waye laarin awọn mejeeji. O ṣalaye pe kii ṣe obinrin nikan lo ma n ṣe oju meji tabi jẹ ọdalẹ ninu irinajo ifẹ, o ni ati ọkunrin ati obinrin lo ni iwa yii lọwọ. O tọka si bi oriṣiriṣi ọkunrin ṣe ma n yi iwa pada si obinrin, ti obinrin naa ko si ni ri oju wọn nilẹ mọ, lẹyin ti ọwọ ọkunrin bẹẹ ba ti tẹ nkan to n wa ninu irinajo ifẹ naa. Ọrọ naa waye lori fidio kan to fi sita, ninu eyi ti oun ati akẹẹgbẹ rẹ, Adedimeji Lateef, ti ṣe ere kekere kan, ninu eyi ti awọn mejeeji ti jẹ ololufẹ. Ninu fidio naa, to jẹ apa kẹrin eto kan ti Adebimpe ma n ṣe, lo pe akori rẹ ni 'DiaryOfAnAfricanWoman EP 4 - MEN ARE SCUM'. Ninu fidio naa, awọn mejeeji fẹran ara wọn pupọ, ṣugbọn lẹyin asiko diẹ, Lateef ko gbe ipe Adebimpe mọ lori foonu. Ibalopọ to ti waye laarin wọn di oyun, amọ niṣe ni Lateef kọ lati gba oyun, to si sọ fun Adebimpe pe, awọn obi oun ko faramọ ki awọn fẹra gẹgẹ bi ọkọ ati iyawo. Adebimpe beere pe ,ki lo de ti awọn ọkunrin kan ma n tan obinrin, nigba ti wọn mọ pe awọn ko ni erongba lati fẹ ẹ sile? O ni ti ọkunrin ba ṣẹṣẹ n fẹ obinrin, o ma n fi aaye silẹ lati wa pẹlu rẹ, ṣugbọn to ba ti kọja lara rẹ tan, aye lati rira ko ni i si mọ. O wa sọ fun awọn ọkunrin pe, ki wọn yi iwa pada, ki wọn o ṣe obinrin bi wọn ba ṣe fẹ ki ọkunrin mii ṣe si ọmọ wọn obinrin.
https://www.bbc.com/yoruba/awon-iroyin-miran-55609158
3politics
Gómìnà Ademola Adeleke bẹ̀rẹ̀ ìyànsípò tirẹ̀, ẹ wo àwọn mẹ́ta tó kọ́kọ́ ṣ’oríire
Ni kete ti Gomina tuntun ti ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke gba eku ida lana ti wọn bura wọle fun lo ti yi ọpọlọpọ nnkan to ba nilẹ pada. Kete to wọ ọfiisi lo ṣe iyansipo gboogi mẹta kan ni ko ju wakati melo kan lọ to ṣe iburawọle. Ninu atẹjade kan ti Adeleke fi sita lọjọ Aiku ni o ti yan alaga kansu ijọba ibilẹ tẹlẹri nilu Osogbo, Ọgbẹni Kassim Akinleye gẹgẹ bii Ọga agba awọn oṣiṣẹ ni Osun.\n\nBakan naa lo buwọlu iyansipo Ọgbẹni Teslim Igbalaye gẹgẹ bii akọwe ijọba ipinlẹ naa nigba ti o ya Ọgbẹni Olawale Rasheed gẹgẹ bi Akọwe agba ijọba.\n“Gbogbo iyansipo yii gbudọ gberasọ ni waransesa.” Bakan naa ni iroyin ni gbogbo iyansipo ti gomina ana, Gboyega Oyetola ṣe ni ọjọ perete to ku ko kuro nipo ni Adeleke ti wọgile tori o ni “o lọwọ ibi ninu.”\nAdeleke ni Gomina Kẹfa ti yoo jẹ nipinlẹ Osun. Niṣe ni ariwo n ho yeee bi gomina ti wọn n bura wọle fun, Ademola Adeleke ṣe n ka ọrọ rẹ jade. Ori papa isere naa kun fọfọ fun ero to fi mọ awọn eekan oloṣelu ati ori ade ti wọn ba wọn pe nibẹ lati lọ yẹ Ademola Adeleke si. Ṣaaju ki Adeleke to bọ sori pepele ni Adajọ ti ṣe iburawọle fun igbakeji rẹ pẹlu iyawo rẹ. Ọpọlọpọ ọmọ ẹgbẹ ati agba oloṣelu ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party lo wa nibi ibura wọle naa. Olu ilu Osogbo nipinle Osun ti gbe awo titun wo saaju ayeye ibura fún Gomina tuntun ti won dibo yan ọjọ kerindinlogun osu keje odun 2022, Seneto Ademola Adeleke to n waye ni oni ojo ketadinlogbon osù kọkànlá. Iyalẹnu lo jẹ fun awọn ololufẹ gbajugbaja ọdọ olorin, David Adeleke to padanu ọmọ rẹ Ifeanyi laipẹ yii pe yoo le ba ẹbi wọn pe nibi eto iburawọle aburo baba rẹ ti wọn sunmọ ara wọn timọ timọ. Akọroyin BBC Yoruba foju gaani rẹ nibẹ. Ni papa iṣere Osogbo stadium, nibi ayẹyẹ ibura fún Gomina tuntun atiwaye ni akoroyin bbc news yoruba ti ri pe gbogbo eto ni ṣepe. Orisiirisii posita Sen Ademola Adeleke ati Igbakeji Gomina Omoba Kola Adewusi ni won fi gbà gbogbo papa isere Osogbo káàkiri. Nibayi, eto aabo ti ibi pápá isere Osogbo wa ni pipe pẹlu awọn ọlọpa ti o ni ihamọra ni kikun ti n ṣọ ibi ti ayẹyẹ naa o ti wáyé. Gẹgẹ bi gbogbo eto ti wọn la kalẹ lati ibẹrẹ ọsẹ yii ṣe ti n lọ ni mẹlọ mẹlọ, oni ọjọ Kẹtadinlọgbọn Oṣu Kọkanla ọdun 20022 ni aṣekagba to si tun jẹ ọjọ ti wọn yoo bura wọle fun gomina wọn tuntun, Ademola, Nurudeen Jackson Adeleke. Bo tilẹ jẹ ke ọwẹ diẹ sẹyin yii ko fi bẹẹ rọgbọ tori gbogbo ẹjọ ti Gomina Oyetola pe Adeleke to si wọ ọ lọ ile ẹjọ, ọjọ naa tun pada ko lonii. Lara awọn nnkan to ti ṣẹlẹ ṣaaju ọjọ yii ni: Ile ẹjọ́ giga ijọba apapọ to wa nílùú Osogbo, nipinlẹ Osun, ti wọgile eto idibo ijọba ibilẹ to waye ni oṣu Kọkanla.\n\nỌjọ karundinlogun, oṣu Kẹwaa, ni ajọ eleto idibo ipinlẹ naa ṣe eto idibo ọhun.\n\nAdajọ Nathaniel Ayo-Emmanuel, sọ ninu idajọ rẹ pe eto idibo naa tako ofin idibo, abala kọkandinlọgbọn ati abala kejilelọgbọn, ti ọdun 2022.\n\nẸgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, lo pe ẹjọ́ tako idibo naa, to si ni ki ile ẹjọ́ pàṣẹ fun ajọ eleto idibo ipinlẹ Osun OSIEC, lati má ṣe eto idibo kankan. Gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola ti kede pe oun ti buwọlu iyansipo awọn osisẹ ijọba toto ọgbọn niye gẹgẹ akọwe agba fun awọn ẹka ijọba ni o ku ọjọ mẹta ti yoo fi po silẹ gẹgẹ gomina ipinlẹ naa.\n\nOrukọ awọn akọwe ọhun lo wa ni atẹjade ti akọwe agba fun ijọba ipinlẹ Osun, Dokita Festus Oyebade buwọlu fun awọn akọroyin lana.\n\nOyetola lo lulẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo Gomina to waye ninu oṣu keje, ti Ademola Adeleke lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP si gbe igba aroke.\n\nSugbọn kete ti ijọba ipinlẹ gbe ikede naa jade ni Gomina tuntun ti ilu dibo yan, Ademole Adeleke fesi pada ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed bu wọlu to si tako igbesẹ naa. Ajọ eleto idibo, INEC, ti sọ pe awọn iwe ẹri gomina tuntun ti wọn dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ko si lọwọ oun mọ.\n\nAlaga ajọ naa nipinlẹ Osun, Ọmọwe Mutiu Agboke, sọ nile ẹjọ to n gbọ ẹsun awuyewuye to waye lẹyin idibo gomina ipinlẹ naa, lọjọ Iṣẹgun pe oun ko ni Form CF 001 ti Adeleke lo lọdun 2018 lọwọ mọ.\n\nỌsẹ to kọja ni ile ẹjọ naa paṣẹ fun INEC, pe ko mu fọọmu naa wa sile ẹjọ, lẹyin ti olupẹjọ, Gomina Gboyega Oyetola bẹ ile ẹjọ lati ṣe bẹẹ.\n\nOṣu Kẹjọ, ọdun 2022, ni Gomina Oyetola ati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, fi iwe ẹsun naa ranṣẹ sile ẹjọ.\n\nForm CF 001 ni fọọmu ti oludije fi forukọ silẹ lati dije, ati awọn iwe ẹri ti Adeleke fun INEC lọdun 2018. Gomina tuntun ti wọn sẹsẹ dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti rọ Gomina to ti fẹ kogba wọle, Gboyega Oyetola pe ko gba kamu pe o ti lulẹ ninu eto idibo gomina to waye ni oṣu Keje, pe ko si simi ariwo ni pipa.\n\nAgbẹnusọ Adeleke, Olawale Rasheed ninu atẹjade to fi ransẹ si Oyetola lẹyin to kede pe oun yoo gba ẹtọ oun, ni pe ko si ẹtọ kankan to fẹ gba lọwọ Adeleke nitori gbogbo ọna ni o fi fi idi rẹ janlẹ ninu eto idibo gomina to waye nipinlẹ Osun.\n\nO ni erongba buburu ni Oyetola ni si awọn eeyan ipinlẹ Osun latari bi o ṣe n fi irọ ati ailotọ ṣe ijọba rẹ.\n\nAdeleke ni kete ti Oyetola ri pe oun ti lulẹ ni o ti bẹrẹ si ni maa ṣe owo ipinlẹ naa basubasu sugbọn ti ile ẹjọ si ti tu ọpọlọpọ irọ ti Oyetola pa fun awọn eeyan. Bi ẹ ko ba gbagbe, lara ajọyọ ti gbajugbaja olorin nni Davido n ṣe nigba ti ibura wọle ẹgbọn rẹ Adeleke sunmọle naa ni pe awọn yoo jọ wa nibẹ ni. Ko pẹ rẹ ni ọlọjọ de ti o mu Ifeanyi ọmọ Davido lọ. Eyi lo faa ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Osun ṣe daro iku ọmọ naa ti wọn si dawọ eto ti o yẹ ki wọn ṣe lọsẹ naa duro.
Gómìnà Ademola Adeleke bẹ̀rẹ̀ ìyànsípò tirẹ̀, ẹ wo àwọn mẹ́ta tó kọ́kọ́ ṣ’oríire Ni kete ti Gomina tuntun ti ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke gba eku ida lana ti wọn bura wọle fun lo ti yi ọpọlọpọ nnkan to ba nilẹ pada. Kete to wọ ọfiisi lo ṣe iyansipo gboogi mẹta kan ni ko ju wakati melo kan lọ to ṣe iburawọle. Ninu atẹjade kan ti Adeleke fi sita lọjọ Aiku ni o ti yan alaga kansu ijọba ibilẹ tẹlẹri nilu Osogbo, Ọgbẹni Kassim Akinleye gẹgẹ bii Ọga agba awọn oṣiṣẹ ni Osun.\n\nBakan naa lo buwọlu iyansipo Ọgbẹni Teslim Igbalaye gẹgẹ bii akọwe ijọba ipinlẹ naa nigba ti o ya Ọgbẹni Olawale Rasheed gẹgẹ bi Akọwe agba ijọba.\n“Gbogbo iyansipo yii gbudọ gberasọ ni waransesa.” Bakan naa ni iroyin ni gbogbo iyansipo ti gomina ana, Gboyega Oyetola ṣe ni ọjọ perete to ku ko kuro nipo ni Adeleke ti wọgile tori o ni “o lọwọ ibi ninu.”\nAdeleke ni Gomina Kẹfa ti yoo jẹ nipinlẹ Osun. Niṣe ni ariwo n ho yeee bi gomina ti wọn n bura wọle fun, Ademola Adeleke ṣe n ka ọrọ rẹ jade. Ori papa isere naa kun fọfọ fun ero to fi mọ awọn eekan oloṣelu ati ori ade ti wọn ba wọn pe nibẹ lati lọ yẹ Ademola Adeleke si. Ṣaaju ki Adeleke to bọ sori pepele ni Adajọ ti ṣe iburawọle fun igbakeji rẹ pẹlu iyawo rẹ. Ọpọlọpọ ọmọ ẹgbẹ ati agba oloṣelu ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party lo wa nibi ibura wọle naa. Olu ilu Osogbo nipinle Osun ti gbe awo titun wo saaju ayeye ibura fún Gomina tuntun ti won dibo yan ọjọ kerindinlogun osu keje odun 2022, Seneto Ademola Adeleke to n waye ni oni ojo ketadinlogbon osù kọkànlá. Iyalẹnu lo jẹ fun awọn ololufẹ gbajugbaja ọdọ olorin, David Adeleke to padanu ọmọ rẹ Ifeanyi laipẹ yii pe yoo le ba ẹbi wọn pe nibi eto iburawọle aburo baba rẹ ti wọn sunmọ ara wọn timọ timọ. Akọroyin BBC Yoruba foju gaani rẹ nibẹ. Ni papa iṣere Osogbo stadium, nibi ayẹyẹ ibura fún Gomina tuntun atiwaye ni akoroyin bbc news yoruba ti ri pe gbogbo eto ni ṣepe. Orisiirisii posita Sen Ademola Adeleke ati Igbakeji Gomina Omoba Kola Adewusi ni won fi gbà gbogbo papa isere Osogbo káàkiri. Nibayi, eto aabo ti ibi pápá isere Osogbo wa ni pipe pẹlu awọn ọlọpa ti o ni ihamọra ni kikun ti n ṣọ ibi ti ayẹyẹ naa o ti wáyé. Gẹgẹ bi gbogbo eto ti wọn la kalẹ lati ibẹrẹ ọsẹ yii ṣe ti n lọ ni mẹlọ mẹlọ, oni ọjọ Kẹtadinlọgbọn Oṣu Kọkanla ọdun 20022 ni aṣekagba to si tun jẹ ọjọ ti wọn yoo bura wọle fun gomina wọn tuntun, Ademola, Nurudeen Jackson Adeleke. Bo tilẹ jẹ ke ọwẹ diẹ sẹyin yii ko fi bẹẹ rọgbọ tori gbogbo ẹjọ ti Gomina Oyetola pe Adeleke to si wọ ọ lọ ile ẹjọ, ọjọ naa tun pada ko lonii. Lara awọn nnkan to ti ṣẹlẹ ṣaaju ọjọ yii ni: Ile ẹjọ́ giga ijọba apapọ to wa nílùú Osogbo, nipinlẹ Osun, ti wọgile eto idibo ijọba ibilẹ to waye ni oṣu Kọkanla.\n\nỌjọ karundinlogun, oṣu Kẹwaa, ni ajọ eleto idibo ipinlẹ naa ṣe eto idibo ọhun.\n\nAdajọ Nathaniel Ayo-Emmanuel, sọ ninu idajọ rẹ pe eto idibo naa tako ofin idibo, abala kọkandinlọgbọn ati abala kejilelọgbọn, ti ọdun 2022.\n\nẸgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, lo pe ẹjọ́ tako idibo naa, to si ni ki ile ẹjọ́ pàṣẹ fun ajọ eleto idibo ipinlẹ Osun OSIEC, lati má ṣe eto idibo kankan. Gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola ti kede pe oun ti buwọlu iyansipo awọn osisẹ ijọba toto ọgbọn niye gẹgẹ akọwe agba fun awọn ẹka ijọba ni o ku ọjọ mẹta ti yoo fi po silẹ gẹgẹ gomina ipinlẹ naa.\n\nOrukọ awọn akọwe ọhun lo wa ni atẹjade ti akọwe agba fun ijọba ipinlẹ Osun, Dokita Festus Oyebade buwọlu fun awọn akọroyin lana.\n\nOyetola lo lulẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo Gomina to waye ninu oṣu keje, ti Ademola Adeleke lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP si gbe igba aroke.\n\nSugbọn kete ti ijọba ipinlẹ gbe ikede naa jade ni Gomina tuntun ti ilu dibo yan, Ademole Adeleke fesi pada ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed bu wọlu to si tako igbesẹ naa. Ajọ eleto idibo, INEC, ti sọ pe awọn iwe ẹri gomina tuntun ti wọn dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ko si lọwọ oun mọ.\n\nAlaga ajọ naa nipinlẹ Osun, Ọmọwe Mutiu Agboke, sọ nile ẹjọ to n gbọ ẹsun awuyewuye to waye lẹyin idibo gomina ipinlẹ naa, lọjọ Iṣẹgun pe oun ko ni Form CF 001 ti Adeleke lo lọdun 2018 lọwọ mọ.\n\nỌsẹ to kọja ni ile ẹjọ naa paṣẹ fun INEC, pe ko mu fọọmu naa wa sile ẹjọ, lẹyin ti olupẹjọ, Gomina Gboyega Oyetola bẹ ile ẹjọ lati ṣe bẹẹ.\n\nOṣu Kẹjọ, ọdun 2022, ni Gomina Oyetola ati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, fi iwe ẹsun naa ranṣẹ sile ẹjọ.\n\nForm CF 001 ni fọọmu ti oludije fi forukọ silẹ lati dije, ati awọn iwe ẹri ti Adeleke fun INEC lọdun 2018. Gomina tuntun ti wọn sẹsẹ dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti rọ Gomina to ti fẹ kogba wọle, Gboyega Oyetola pe ko gba kamu pe o ti lulẹ ninu eto idibo gomina to waye ni oṣu Keje, pe ko si simi ariwo ni pipa.\n\nAgbẹnusọ Adeleke, Olawale Rasheed ninu atẹjade to fi ransẹ si Oyetola lẹyin to kede pe oun yoo gba ẹtọ oun, ni pe ko si ẹtọ kankan to fẹ gba lọwọ Adeleke nitori gbogbo ọna ni o fi fi idi rẹ janlẹ ninu eto idibo gomina to waye nipinlẹ Osun.\n\nO ni erongba buburu ni Oyetola ni si awọn eeyan ipinlẹ Osun latari bi o ṣe n fi irọ ati ailotọ ṣe ijọba rẹ.\n\nAdeleke ni kete ti Oyetola ri pe oun ti lulẹ ni o ti bẹrẹ si ni maa ṣe owo ipinlẹ naa basubasu sugbọn ti ile ẹjọ si ti tu ọpọlọpọ irọ ti Oyetola pa fun awọn eeyan. Bi ẹ ko ba gbagbe, lara ajọyọ ti gbajugbaja olorin nni Davido n ṣe nigba ti ibura wọle ẹgbọn rẹ Adeleke sunmọle naa ni pe awọn yoo jọ wa nibẹ ni. Ko pẹ rẹ ni ọlọjọ de ti o mu Ifeanyi ọmọ Davido lọ. Eyi lo faa ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Osun ṣe daro iku ọmọ naa ti wọn si dawọ eto ti o yẹ ki wọn ṣe lọsẹ naa duro.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cxweewdenpgo
4religion
Ariwo kò yẹ kóo máa gbé Kùránì dání pẹ̀lú iṣẹ́ aṣẹ́wó tí ò ń se ní wọ́n pa kí wọ́n tó dáná sun òkú náà
Ọkùnrin mẹ́ta gún aṣẹ́wó pa, dáná sun okù rẹ̀ torí wọ́n ba Quran nínú yàrá rẹ̀ Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti gbe awọn ọkunrin mẹta kan lọ ile ẹjọ losi ẹsun pe wọn lu obinrin aṣẹwo kan pa, ti wọn tun dana sun oku rẹ. Awọn afurasi naa gbe igbesẹ ọhun lẹyin ti wọn ba Quran ninu yara rẹ. Abubakar Musa, Surajo Yusuf àti Sarauta Monsur ni wọn dana sun oku Hanatu Saliu ni agbegbe Alaba Rago ni ipinle Eko Iroyin ni ọkan lara awọn afurasi naa ti kọkọ ba ologbe naa, Hannah Saliu lopọ, to si fun ni ẹgbẹrun kan naira gẹgẹ bi owo iṣẹ rẹ. Amọ oloogbe naa ṣakiyesi pe ẹgbẹrun marun un naira ti poora ninu ile oun lẹyin ti wọn ni ajọṣepọ tan. Eyii lo mu ki oloogbe naa sare tọ onibara rẹ ọhun lọ, to si fẹsun kan pe oun lo ji owo naa, sugbọn ọrọ naa di ariwo nla. Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, onibara naa ko awọn ọrẹ rẹ lọ sinu yara oloogbe ọhun lati wa owo to ni o oun ji. Ibi ti wọn ti n wa owo yii ni wọn ti ṣawari iwe mimọ awọn Musulumi, Al-Qur’an, labẹ irọri rẹ. Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ fun awọn akọroyin pe wọn bi oloogbe naa lawọn ibere nipa bi Quran ṣe de inu yara rẹ pẹlu pe iṣẹ aṣẹwo lo n ṣe, ti awọn afurasi naa si faraya lori ohun ti wọn foju ganni. Ẹni naa ni “Ohun to ṣẹlẹ ni pe, aṣẹwo ni obinrin naa, okunrin ọhun ji ẹgbẹrun marun un rẹ, o si le lere lati bere owo naa lọwọ rẹ.” “Onibrara naa wa sọ fun oloogbe naa pe ki wọn lọ wa yara rẹ lati mọ boya owo to n wa ṣi wa ninu ninu yara rẹ.” “Ibi ti wọn ti n wa inu yara ọhun ni wọn ti ri Quran labẹ irọri rẹ ti wọn si n bere lọwọ rẹ ohun ti Quran n ṣe ninu ile rẹ gẹgẹ bii aṣẹwo.” “Lẹyin naa ni awọn ọkunrin ọhun to jẹ ọmọ Oke ọya gun lọbẹ, ti wọn si tun dana sun oku rẹ.” “Iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Aba Rego ti ọpọ awọn Hausa n gbe, Hausa si ni oloogbe naa pẹlu.” Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin lo fidi iroyin naa mulẹ.
Ariwo kò yẹ kóo máa gbé Kùránì dání pẹ̀lú iṣẹ́ aṣẹ́wó tí ò ń se ní wọ́n pa kí wọ́n tó dáná sun òkú náà Ọkùnrin mẹ́ta gún aṣẹ́wó pa, dáná sun okù rẹ̀ torí wọ́n ba Quran nínú yàrá rẹ̀ Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti gbe awọn ọkunrin mẹta kan lọ ile ẹjọ losi ẹsun pe wọn lu obinrin aṣẹwo kan pa, ti wọn tun dana sun oku rẹ. Awọn afurasi naa gbe igbesẹ ọhun lẹyin ti wọn ba Quran ninu yara rẹ. Abubakar Musa, Surajo Yusuf àti Sarauta Monsur ni wọn dana sun oku Hanatu Saliu ni agbegbe Alaba Rago ni ipinle Eko Iroyin ni ọkan lara awọn afurasi naa ti kọkọ ba ologbe naa, Hannah Saliu lopọ, to si fun ni ẹgbẹrun kan naira gẹgẹ bi owo iṣẹ rẹ. Amọ oloogbe naa ṣakiyesi pe ẹgbẹrun marun un naira ti poora ninu ile oun lẹyin ti wọn ni ajọṣepọ tan. Eyii lo mu ki oloogbe naa sare tọ onibara rẹ ọhun lọ, to si fẹsun kan pe oun lo ji owo naa, sugbọn ọrọ naa di ariwo nla. Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, onibara naa ko awọn ọrẹ rẹ lọ sinu yara oloogbe ọhun lati wa owo to ni o oun ji. Ibi ti wọn ti n wa owo yii ni wọn ti ṣawari iwe mimọ awọn Musulumi, Al-Qur’an, labẹ irọri rẹ. Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ fun awọn akọroyin pe wọn bi oloogbe naa lawọn ibere nipa bi Quran ṣe de inu yara rẹ pẹlu pe iṣẹ aṣẹwo lo n ṣe, ti awọn afurasi naa si faraya lori ohun ti wọn foju ganni. Ẹni naa ni “Ohun to ṣẹlẹ ni pe, aṣẹwo ni obinrin naa, okunrin ọhun ji ẹgbẹrun marun un rẹ, o si le lere lati bere owo naa lọwọ rẹ.” “Onibrara naa wa sọ fun oloogbe naa pe ki wọn lọ wa yara rẹ lati mọ boya owo to n wa ṣi wa ninu ninu yara rẹ.” “Ibi ti wọn ti n wa inu yara ọhun ni wọn ti ri Quran labẹ irọri rẹ ti wọn si n bere lọwọ rẹ ohun ti Quran n ṣe ninu ile rẹ gẹgẹ bii aṣẹwo.” “Lẹyin naa ni awọn ọkunrin ọhun to jẹ ọmọ Oke ọya gun lọbẹ, ti wọn si tun dana sun oku rẹ.” “Iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Aba Rego ti ọpọ awọn Hausa n gbe, Hausa si ni oloogbe naa pẹlu.” Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin lo fidi iroyin naa mulẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cevxxkqnlkwo
1entertainment
Mayowa Omoniyi: Olùkọ́ rẹ̀ ní òun ni atagìtá ''Hawaiian guitar'' tó kéré jùlọ lágbàáyé
Omo ti yoo ba jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu samu samu. Bẹẹ ni ọrọ Mayowa Omoniyi jẹ, ọmọ ọdun mẹtala to pegede ju agbalagba miran lọ ninu gita tita. Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Mayowa ni baba oun lo kọ oun bi wọn se n ta jita, bakan naa si ni oun le tẹ duuru pẹlu. O ni ko si orin Ebenezer Obey, Sunny Ade, takansufe tabi orin ẹmi ti oun ko le tẹ jita si gẹgẹ bii akọsẹmọsẹ atajita. Nigba tawọn naa n sọrọ nipa bi Mayowa ti dangajia si ninu jita tita, Taiwo Omoniyi, tii se baba Mayowa ati ibeji rẹ, Kehinde fidi rẹ mulẹ pe Mayowa ti kọja ipo tawọn wa ninu jita tita. Bakan naa ni olukọ to n kọ Mayowa ni ohun elo orin, Samson Akinola ni iwadi oun fihan pe lọwọ lọwọ bayii, Mayowa Omoniyi ni atajita to kere julọ lagbayee. O ni ko si irufẹ orin ti Mayowa ko le ta jita si.
Mayowa Omoniyi: Olùkọ́ rẹ̀ ní òun ni atagìtá ''Hawaiian guitar'' tó kéré jùlọ lágbàáyé Omo ti yoo ba jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu samu samu. Bẹẹ ni ọrọ Mayowa Omoniyi jẹ, ọmọ ọdun mẹtala to pegede ju agbalagba miran lọ ninu gita tita. Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Mayowa ni baba oun lo kọ oun bi wọn se n ta jita, bakan naa si ni oun le tẹ duuru pẹlu. O ni ko si orin Ebenezer Obey, Sunny Ade, takansufe tabi orin ẹmi ti oun ko le tẹ jita si gẹgẹ bii akọsẹmọsẹ atajita. Nigba tawọn naa n sọrọ nipa bi Mayowa ti dangajia si ninu jita tita, Taiwo Omoniyi, tii se baba Mayowa ati ibeji rẹ, Kehinde fidi rẹ mulẹ pe Mayowa ti kọja ipo tawọn wa ninu jita tita. Bakan naa ni olukọ to n kọ Mayowa ni ohun elo orin, Samson Akinola ni iwadi oun fihan pe lọwọ lọwọ bayii, Mayowa Omoniyi ni atajita to kere julọ lagbayee. O ni ko si irufẹ orin ti Mayowa ko le ta jita si.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-54083389
2health
Snake bite in toilet: Kí ló yẹ kóo sáré ṣe bí ejò bá ṣá ọ jẹ?
E ku ewu ọdun Keresimesi ati ti ọdun tuntun ni ọpọ n kira wọn lasiko yii ni ọpọ rinrinajo lo si abule ati ẹyin odi lati lọ ṣe ọdun pẹlu ẹbi, ara ati iyekan wọn. Bakan naa ni awọn eeyan tun n fi sori ayelujara pe o ṣeeṣe ki ọpọ ejo afayafa maa jade wa ya oorun nitori ọyẹ to gbode kan lasiko yii. Eyi lo mu ki BBC Yoruba se akojopó ọna mẹfa ti ejo ko ṣe ni le bu ọjẹ lasiko pọpọṣinṣin ọdun yii. Ọna akọkọ ni ki eniyan ri pe ile igbọnsẹ tabi baluwe ko famimọra tabi dẹrun fun ejo lati wọle si inu rẹ Saaju ni iroyin jade losu kan se\yion lori ọrọ ejo. Pẹlu bi iroyin ṣe gbode kan lori bi ejo ṣe n dede wọ inu ile awọn eeyan tabi ki awọn eeyan dede ri ejo ko yọju lati inu ile igbọnsẹ wọn lo mu ki awọn eeyan maa beere ibeere ohu to yẹ lati ṣe bi ejo ba ṣa eeyan jẹ ati bi wọn ṣe lee dena rẹ. Ko si ẹni to lee mọ idi ti ejo fi wa ọna rapala wọ inu ile igbọnsẹ. Oṣiṣẹ awọn ọpa paipu to wọ inu ile ti BBC ba sọrọ to maa n ba awọn eeyan ṣiṣẹ inu yara igbọnsẹ sọ pe ọpọlọpọ eeyan lo maa n ro pe paipu to jade lati inu ile igbọnsẹ maa n ni omi ninu amọ o ni ko ri bẹẹ. Àwọn àjòjì ṣá obìnrin tó ń lọ gbálẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Deeper Life pa, ẹ̀jẹ̀ bo gbogbo ara rẹ̀ Ejò bu ìdí obìnrin kan jẹ nínú ilé ìgbọ̀nsẹ Kí ló mú ọkùnrin kan fi ejò Sèbé olóró pa aya rẹ̀ lójú oorun? Ohun márùn ún tí ejò ń jẹ Ejò bu abóyún jẹ nílé ìyàgbẹ́, ó kú pẹ̀lú oyún oṣù mẹ́jọ ní Kaduna "Ọna bi wọn ṣe ṣe koto igbọnsẹ ni pe inu rẹ nikan ni omi maa n wa ati pe igba ti omi maa n wọ inu paipu ni igba ti eeyan ba tẹ omi lati ṣan igbẹ danu lẹyin teeyan ba ya igbẹ tan". O tun sọ pe lara ọna kan ti ejo fi maa n wọ inu paipu ile igbọnsẹ ni yala lati inu tanki to wa ni ita tabi inu "soakaway" ti igbẹ ati itọ n lọ to ba ti fọ nibi kan tabi ti alafo kan ṣi silẹ fun ejo lati wọle. Gẹgẹ bi eyi ṣe wa n kọ awọn eeyan lominu bi ejo ṣe n san awọn eeyan ni adugbo wọn, ajọ isọkan agbaye, WHO ti n fi awọn imọran sita lori ohun to yẹ keeyan ṣe bi iriri yii ba ṣẹlẹ. - Gbe eeyan naa kuro nibi ti ejo ti san an tabi ki o le ejo naa kuro to ba ṣi yọju. - Yọ ohun kohun to ba le dain kuro ni oju ibi ti ejo ti bu ni naa jẹ - nkan bii oruka tabi ẹgba ọwọ tori o lee da wahala mii silẹ bi oju sisan yẹn ba wu. - Jẹ ki ẹni naa fi ara balẹ tori kii ṣe ọpọlọpọ gbogbo ejo sisan naa ni yoo fa iku ẹni naa loju ẹsẹ. - Ma jẹ ki ẹni naa gbera rara, iwọ ni koo gbe ẹni naa lọ si ile ibudo ilera kia kia. - Tẹ oju egbo ti ejo san naa pẹlu agbara - Ma ṣe lo oogun ibilẹ. - Ẹni naa le lo oogun oyinbo Paracetemol lati din ara riro ku tori bi ejo ba san ni jẹ, o maa n dun eeyan gidi gan. - Yi oju ni naa si ẹgbẹ tori ti o ba fẹ bi eebi. - Rii daju pe o n woo pe ẹni naa ṣi n mi Wo ọ̀ná tí àwọn okùnrin lè gbà ṣe ìfètòsọ́mọbíbí láì lo kọ́ndọ́ọ̀mù lásìkò ìbálòpọ̀ Kéére o! Wọ́n ti rí èèyàn méjì tó ní ẹ̀yà Covid-19 tuntun, "Omicron variant" nínú báàlù Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí àwọn olólùfẹ́ yìí tí wọ́n bá okú wọn ní ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wọn Irọ́ ni pé ìjọba Naijiria ti n ṣètò láti gbá Sunday Igboho wá sí Naijiria - Ilana Omo Oodua Rii daju pe ina wa ni titan nigba ti o ba fẹ lo ile igbọnsẹ ki o le wo inu koto igbọnsẹ wo koo to gbe idi lee. Ma sọ ile igbọnsẹ rẹ di ibi ikẹru si - rii pe o n wa ni mimọ toni toni ni gbogbo igba. Lẹẹkọọkan, maa ṣe ayẹwo paipu, "soakaway", iho salanga, inu orule, ogiri to ba ni iho tabi to ba la tabi awọn nkan to ni ọmọri to ti ṣi silẹ. Ṣe atunṣe wọn lọgan ti o ba ti ri wọn.
Snake bite in toilet: Kí ló yẹ kóo sáré ṣe bí ejò bá ṣá ọ jẹ? E ku ewu ọdun Keresimesi ati ti ọdun tuntun ni ọpọ n kira wọn lasiko yii ni ọpọ rinrinajo lo si abule ati ẹyin odi lati lọ ṣe ọdun pẹlu ẹbi, ara ati iyekan wọn. Bakan naa ni awọn eeyan tun n fi sori ayelujara pe o ṣeeṣe ki ọpọ ejo afayafa maa jade wa ya oorun nitori ọyẹ to gbode kan lasiko yii. Eyi lo mu ki BBC Yoruba se akojopó ọna mẹfa ti ejo ko ṣe ni le bu ọjẹ lasiko pọpọṣinṣin ọdun yii. Ọna akọkọ ni ki eniyan ri pe ile igbọnsẹ tabi baluwe ko famimọra tabi dẹrun fun ejo lati wọle si inu rẹ Saaju ni iroyin jade losu kan se\yion lori ọrọ ejo. Pẹlu bi iroyin ṣe gbode kan lori bi ejo ṣe n dede wọ inu ile awọn eeyan tabi ki awọn eeyan dede ri ejo ko yọju lati inu ile igbọnsẹ wọn lo mu ki awọn eeyan maa beere ibeere ohu to yẹ lati ṣe bi ejo ba ṣa eeyan jẹ ati bi wọn ṣe lee dena rẹ. Ko si ẹni to lee mọ idi ti ejo fi wa ọna rapala wọ inu ile igbọnsẹ. Oṣiṣẹ awọn ọpa paipu to wọ inu ile ti BBC ba sọrọ to maa n ba awọn eeyan ṣiṣẹ inu yara igbọnsẹ sọ pe ọpọlọpọ eeyan lo maa n ro pe paipu to jade lati inu ile igbọnsẹ maa n ni omi ninu amọ o ni ko ri bẹẹ. Àwọn àjòjì ṣá obìnrin tó ń lọ gbálẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Deeper Life pa, ẹ̀jẹ̀ bo gbogbo ara rẹ̀ Ejò bu ìdí obìnrin kan jẹ nínú ilé ìgbọ̀nsẹ Kí ló mú ọkùnrin kan fi ejò Sèbé olóró pa aya rẹ̀ lójú oorun? Ohun márùn ún tí ejò ń jẹ Ejò bu abóyún jẹ nílé ìyàgbẹ́, ó kú pẹ̀lú oyún oṣù mẹ́jọ ní Kaduna "Ọna bi wọn ṣe ṣe koto igbọnsẹ ni pe inu rẹ nikan ni omi maa n wa ati pe igba ti omi maa n wọ inu paipu ni igba ti eeyan ba tẹ omi lati ṣan igbẹ danu lẹyin teeyan ba ya igbẹ tan". O tun sọ pe lara ọna kan ti ejo fi maa n wọ inu paipu ile igbọnsẹ ni yala lati inu tanki to wa ni ita tabi inu "soakaway" ti igbẹ ati itọ n lọ to ba ti fọ nibi kan tabi ti alafo kan ṣi silẹ fun ejo lati wọle. Gẹgẹ bi eyi ṣe wa n kọ awọn eeyan lominu bi ejo ṣe n san awọn eeyan ni adugbo wọn, ajọ isọkan agbaye, WHO ti n fi awọn imọran sita lori ohun to yẹ keeyan ṣe bi iriri yii ba ṣẹlẹ. - Gbe eeyan naa kuro nibi ti ejo ti san an tabi ki o le ejo naa kuro to ba ṣi yọju. - Yọ ohun kohun to ba le dain kuro ni oju ibi ti ejo ti bu ni naa jẹ - nkan bii oruka tabi ẹgba ọwọ tori o lee da wahala mii silẹ bi oju sisan yẹn ba wu. - Jẹ ki ẹni naa fi ara balẹ tori kii ṣe ọpọlọpọ gbogbo ejo sisan naa ni yoo fa iku ẹni naa loju ẹsẹ. - Ma jẹ ki ẹni naa gbera rara, iwọ ni koo gbe ẹni naa lọ si ile ibudo ilera kia kia. - Tẹ oju egbo ti ejo san naa pẹlu agbara - Ma ṣe lo oogun ibilẹ. - Ẹni naa le lo oogun oyinbo Paracetemol lati din ara riro ku tori bi ejo ba san ni jẹ, o maa n dun eeyan gidi gan. - Yi oju ni naa si ẹgbẹ tori ti o ba fẹ bi eebi. - Rii daju pe o n woo pe ẹni naa ṣi n mi Wo ọ̀ná tí àwọn okùnrin lè gbà ṣe ìfètòsọ́mọbíbí láì lo kọ́ndọ́ọ̀mù lásìkò ìbálòpọ̀ Kéére o! Wọ́n ti rí èèyàn méjì tó ní ẹ̀yà Covid-19 tuntun, "Omicron variant" nínú báàlù Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí àwọn olólùfẹ́ yìí tí wọ́n bá okú wọn ní ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wọn Irọ́ ni pé ìjọba Naijiria ti n ṣètò láti gbá Sunday Igboho wá sí Naijiria - Ilana Omo Oodua Rii daju pe ina wa ni titan nigba ti o ba fẹ lo ile igbọnsẹ ki o le wo inu koto igbọnsẹ wo koo to gbe idi lee. Ma sọ ile igbọnsẹ rẹ di ibi ikẹru si - rii pe o n wa ni mimọ toni toni ni gbogbo igba. Lẹẹkọọkan, maa ṣe ayẹwo paipu, "soakaway", iho salanga, inu orule, ogiri to ba ni iho tabi to ba la tabi awọn nkan to ni ọmọri to ti ṣi silẹ. Ṣe atunṣe wọn lọgan ti o ba ti ri wọn.
https://www.bbc.com/yoruba/59449393
5sports
AFCON2019: Idije òní á yàtọ̀ láàrin Super Eagles ati BafanaBafana
A n gbe ife ẹyẹ AFCON bọ wa sile ni. Lala maa lu ni alẹ oni nigba ti Bafana Bafana ẹgbẹ agbabọọlu South Africa maa gbena woju Super Eagles ti Naijiria. Idije AFCON ti ilẹ Adulawọ ṣi n lọ lọwọ ni orilẹ-ede Egypt to n gbalejo ẹ. Ọpọ ninu awọn ọmọ Naijiria gba pe ori Aare Buhari maa n gba ife ẹyẹ pe ati pé pẹlu adura, o maa ja si ọpẹ.
AFCON2019: Idije òní á yàtọ̀ láàrin Super Eagles ati BafanaBafana A n gbe ife ẹyẹ AFCON bọ wa sile ni. Lala maa lu ni alẹ oni nigba ti Bafana Bafana ẹgbẹ agbabọọlu South Africa maa gbena woju Super Eagles ti Naijiria. Idije AFCON ti ilẹ Adulawọ ṣi n lọ lọwọ ni orilẹ-ede Egypt to n gbalejo ẹ. Ọpọ ninu awọn ọmọ Naijiria gba pe ori Aare Buhari maa n gba ife ẹyẹ pe ati pé pẹlu adura, o maa ja si ọpẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/48933496
4religion
Insecurity In Nigeria: Ẹ yàgò fún ádùrá ṣiṣe nínú igbó kí ẹ má kò sí ọwọ àwọn ajínigbe-Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti kilọ fawọn olujọsin lati yago fun ṣiṣe adura ninu igbo, ki wọn ma ba ko si ọwọ awọn ajinigbe. Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita gba latọwọ alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, ileesẹ ọlọpaa ni ilu ti le kọja ki eeyan maa fi ara rẹ sinu ewu adura ṣiṣe ninu igbo. Oyeyemi sọ pe bo tilẹ jẹ wi pe awọn araalu lẹtọ lati jọsin, amọ wọn ko gbọdọ maa ṣe adura lawọn agbegbe to ba da paro paro. O ni iwe mimọ ni bi a baa n ṣe adura, ki a ma sun asunpara bakan naa. Lọpọ awọn igbo to wa ni ipinlẹ Ogun, ṣiṣe eto isin adura paapa fawọn ẹlẹsin Kristẹni jẹ nkan to wọpọ. Ipenija aabo lẹnu ọjọ mẹta yii si ṣe okunfa bi awọn ajinigbe ti ṣe n sa si abẹ igbo kijikiji lati ji awọn eeyan gbe, nibi ti wọn ba ti n ṣe ijọsin tabi iṣẹ wọn. Ni ipinlẹ Ogun paapa lawọn ilu to ba sun mọ igbo tabi ibode pẹlu orileede mii bi Benin, iṣẹlẹ ijinigbe ko jẹ tuntun. Oyeyemi ṣalaye pe, iṣẹ ipese aabo yii, ti gbogbo ara ilu nii ṣe, tori naa, kawọn araalu daabo bo ara wọn ati dukia wọn. Amọ ṣa, o ni ti o ba wa di dandan ki wọn ṣe ijọsin adura wọn yii, ki wọn kan si agọ ọlọpaa to wa ni itosi wọn fun aabo tabi imọran to peye.
Insecurity In Nigeria: Ẹ yàgò fún ádùrá ṣiṣe nínú igbó kí ẹ má kò sí ọwọ àwọn ajínigbe-Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti kilọ fawọn olujọsin lati yago fun ṣiṣe adura ninu igbo, ki wọn ma ba ko si ọwọ awọn ajinigbe. Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita gba latọwọ alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, ileesẹ ọlọpaa ni ilu ti le kọja ki eeyan maa fi ara rẹ sinu ewu adura ṣiṣe ninu igbo. Oyeyemi sọ pe bo tilẹ jẹ wi pe awọn araalu lẹtọ lati jọsin, amọ wọn ko gbọdọ maa ṣe adura lawọn agbegbe to ba da paro paro. O ni iwe mimọ ni bi a baa n ṣe adura, ki a ma sun asunpara bakan naa. Lọpọ awọn igbo to wa ni ipinlẹ Ogun, ṣiṣe eto isin adura paapa fawọn ẹlẹsin Kristẹni jẹ nkan to wọpọ. Ipenija aabo lẹnu ọjọ mẹta yii si ṣe okunfa bi awọn ajinigbe ti ṣe n sa si abẹ igbo kijikiji lati ji awọn eeyan gbe, nibi ti wọn ba ti n ṣe ijọsin tabi iṣẹ wọn. Ni ipinlẹ Ogun paapa lawọn ilu to ba sun mọ igbo tabi ibode pẹlu orileede mii bi Benin, iṣẹlẹ ijinigbe ko jẹ tuntun. Oyeyemi ṣalaye pe, iṣẹ ipese aabo yii, ti gbogbo ara ilu nii ṣe, tori naa, kawọn araalu daabo bo ara wọn ati dukia wọn. Amọ ṣa, o ni ti o ba wa di dandan ki wọn ṣe ijọsin adura wọn yii, ki wọn kan si agọ ọlọpaa to wa ni itosi wọn fun aabo tabi imọran to peye.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58627614
3politics
APC: O jẹ́ tètè jẹ́wọ́ àwọn tó rán ọ níṣẹ́ torí àwa kìí fún apààyàn lówó
Yoruba ni to ba buru tan, iwọ nikan ni yoo ku. Bẹẹ lọrọ ri fun afurasi ajinigbe kan ti ẹnu ko sin lara rẹ lẹnu ọjọ mẹta yii, Hamisu Bala, ti gbogbo eeyan mọ si Wadume, ẹni to kede pe ẹgbẹ oselu APC fun oun ni miliọnu mẹtala naira lasiko eto idibo apapọ to kọja. Bẹẹ ba gbagbe, afurasi yii ni awọn ọlọpa fẹ gbe nipinlẹ Taraba, amọ ti awọn ologun gbaa silẹ, ti wọn si gbẹmi ọlọpa mẹta ati araalu kan lasiko isẹlẹ naa. Nigba ti ọwọ wa tẹ Wadume, lo ba figbe ta pe oun kii se apaayan abi ajinigbe rara, oloselu ni oun, ti ẹgbẹ oselu APC si mọ oun bii ẹni mọ owo, koda wọn fun oun ni miliọnu mẹtala naira lasiko ibo to kọja fun ipolongo ibo, amọ ti oun na miliọnu meje naira nibẹ. Sugbọn niwọn igba to jẹ pe oku ni eeyan pa irọ mọ ti kii lee fọhun, ẹgbẹ oselu APC ti wa kigbe sita fun Wadume pe, yoo dara ko tete sọ awọn to ran nisẹ ibi nitori APC kii fun awọn apaayan ati ajinigbe ni owo. Lanre Issa Onilu, tii se akọwe ipolongo apapọ fun ẹgbẹ APC salaye pe, ọrọ Wadume dabi afomọ to n wa gbongbo ti yoo so mọ ni lasiko to fẹ subu sinu odo, o si di dandan ki Wadume to n koju idajọ fẹ wa awọn ti yoo fẹyin ti ni. "Ẹgbẹ tiwa kii ya owo sọtọ fun awọn janduku. Asiko yii yatọ si igba ti ẹgbẹ to n sejọba maa n tọwọ bọ apo ilu lati fi owo gbọ bukata ipolongo ibo ati idibo pẹlu, bi ọwọ eku ẹgbẹ oselu wa se mọ, lo fi n họri lasiko yii." Onilu ni, taa ba gbọ ohun ti Wadume sọ yii daada, a jẹ pe ọmọ ẹgbẹ APC ni yoo jẹ pẹlu awọn alaye to se.
APC: O jẹ́ tètè jẹ́wọ́ àwọn tó rán ọ níṣẹ́ torí àwa kìí fún apààyàn lówó Yoruba ni to ba buru tan, iwọ nikan ni yoo ku. Bẹẹ lọrọ ri fun afurasi ajinigbe kan ti ẹnu ko sin lara rẹ lẹnu ọjọ mẹta yii, Hamisu Bala, ti gbogbo eeyan mọ si Wadume, ẹni to kede pe ẹgbẹ oselu APC fun oun ni miliọnu mẹtala naira lasiko eto idibo apapọ to kọja. Bẹẹ ba gbagbe, afurasi yii ni awọn ọlọpa fẹ gbe nipinlẹ Taraba, amọ ti awọn ologun gbaa silẹ, ti wọn si gbẹmi ọlọpa mẹta ati araalu kan lasiko isẹlẹ naa. Nigba ti ọwọ wa tẹ Wadume, lo ba figbe ta pe oun kii se apaayan abi ajinigbe rara, oloselu ni oun, ti ẹgbẹ oselu APC si mọ oun bii ẹni mọ owo, koda wọn fun oun ni miliọnu mẹtala naira lasiko ibo to kọja fun ipolongo ibo, amọ ti oun na miliọnu meje naira nibẹ. Sugbọn niwọn igba to jẹ pe oku ni eeyan pa irọ mọ ti kii lee fọhun, ẹgbẹ oselu APC ti wa kigbe sita fun Wadume pe, yoo dara ko tete sọ awọn to ran nisẹ ibi nitori APC kii fun awọn apaayan ati ajinigbe ni owo. Lanre Issa Onilu, tii se akọwe ipolongo apapọ fun ẹgbẹ APC salaye pe, ọrọ Wadume dabi afomọ to n wa gbongbo ti yoo so mọ ni lasiko to fẹ subu sinu odo, o si di dandan ki Wadume to n koju idajọ fẹ wa awọn ti yoo fẹyin ti ni. "Ẹgbẹ tiwa kii ya owo sọtọ fun awọn janduku. Asiko yii yatọ si igba ti ẹgbẹ to n sejọba maa n tọwọ bọ apo ilu lati fi owo gbọ bukata ipolongo ibo ati idibo pẹlu, bi ọwọ eku ẹgbẹ oselu wa se mọ, lo fi n họri lasiko yii." Onilu ni, taa ba gbọ ohun ti Wadume sọ yii daada, a jẹ pe ọmọ ẹgbẹ APC ni yoo jẹ pẹlu awọn alaye to se.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49463848
2health
Coronavirus in Nigeria: Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọ̀nà láti dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ Coronavirus
Aarun Coronavirus ti wọ orilẹede Naijiria bayii, eyi kii sii ṣe iroyin tuntun mọ bayii. Amọ, bi ọrọ ti ṣe jẹ bayii, awọn ọna wo ni o lee fi daabo bo ara rẹ lọwọ arun yii. Gẹgẹ bi atẹjade ajọ ilera agbaye, WHO, lootọ orilẹ€de China ni arun yii ti gbera ṣugbọn awọn orilẹede to ti ran de ti pọ, leyi ti orilẹede Naijiria naa si ti wa darapọ mọ wọn bayii. Pupọ awọn to ba kọlu aarun yii maa n ni ailera diẹ, wọn o si tun pada bọ sipo ilera wọn pada, ṣugbọn bẹẹ kọ lọrọ ri fun fun awọn miran. Eyi ni ọna ti o lee gba daabo bo ara rẹ atawọn miran lọwọ arun Coronavirus: Rii daju pe o n fọ ọwọ rẹ loorekoore pẹlu ọṣẹ ifọwọ ati omi to mọ. Ki ni idi? Fifọ ọwọ rẹ pẹlu ọṣẹ ati omi mimọ yoo pa awọn kokoro arun to n gbe ni ọwọ rẹ. Rii daju pe o rin jina fun bi iwọ ẹsẹ bata mẹta si ẹnikẹni ti o ba kẹẹfin pe o n wukọ tabi ṣe ọfinkin. Ki ni idi? Bi eniyan ba n wuks tabi sin, iwọn omi diẹ to ba n jade ni imu tabi ẹnu wọn lee ni koko arun yii. Bi o ba wa sunmọ wọn ju bi o ti yẹ lọ, iwọ naa lee koo simu pẹlu kokoro arun yii bi o ba jẹ pe onitọun ni kokoro arun COVID-19. Ọwọ rẹ ti o ti fi kan oniruuru nnkan lee ti kan kokoro arun yii. Bi ọwọ ba si ti kan an , o lee taare rẹ si oju rẹ, imu tabi ẹnu rẹ. Nipasẹ bẹẹ kokoro arun yii lee wọ ara rẹ ki o si sọ ọ di alailera. Duro si ile rẹ bi o ba ṣakiyesi pe ara rẹ ko ya. Bi o ba ni iba, ikọ ati iṣoro lati mi, tete tọ awọn oniṣegun oyinbo lọ fun ayẹwo ati itọju. Pe wọn ni ile iwosan naa silẹ, ki wọn lee ti gbaradi de ọ. Oniruuru iroyin lo n lọ kaakiri lori ọna ti o lee gba dena arun yii ati ohun gbogbo ti o nilo lati mọ nipa COVID-19 ti a mọ si coronavirus. Ma si ṣe gbagbe lati maa tẹle awọnilana eto ilera tawọn alaṣẹ ijọba lagbegbe rẹ ba fi sita. Awọn
Coronavirus in Nigeria: Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọ̀nà láti dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ Coronavirus Aarun Coronavirus ti wọ orilẹede Naijiria bayii, eyi kii sii ṣe iroyin tuntun mọ bayii. Amọ, bi ọrọ ti ṣe jẹ bayii, awọn ọna wo ni o lee fi daabo bo ara rẹ lọwọ arun yii. Gẹgẹ bi atẹjade ajọ ilera agbaye, WHO, lootọ orilẹ€de China ni arun yii ti gbera ṣugbọn awọn orilẹede to ti ran de ti pọ, leyi ti orilẹede Naijiria naa si ti wa darapọ mọ wọn bayii. Pupọ awọn to ba kọlu aarun yii maa n ni ailera diẹ, wọn o si tun pada bọ sipo ilera wọn pada, ṣugbọn bẹẹ kọ lọrọ ri fun fun awọn miran. Eyi ni ọna ti o lee gba daabo bo ara rẹ atawọn miran lọwọ arun Coronavirus: Rii daju pe o n fọ ọwọ rẹ loorekoore pẹlu ọṣẹ ifọwọ ati omi to mọ. Ki ni idi? Fifọ ọwọ rẹ pẹlu ọṣẹ ati omi mimọ yoo pa awọn kokoro arun to n gbe ni ọwọ rẹ. Rii daju pe o rin jina fun bi iwọ ẹsẹ bata mẹta si ẹnikẹni ti o ba kẹẹfin pe o n wukọ tabi ṣe ọfinkin. Ki ni idi? Bi eniyan ba n wuks tabi sin, iwọn omi diẹ to ba n jade ni imu tabi ẹnu wọn lee ni koko arun yii. Bi o ba wa sunmọ wọn ju bi o ti yẹ lọ, iwọ naa lee koo simu pẹlu kokoro arun yii bi o ba jẹ pe onitọun ni kokoro arun COVID-19. Ọwọ rẹ ti o ti fi kan oniruuru nnkan lee ti kan kokoro arun yii. Bi ọwọ ba si ti kan an , o lee taare rẹ si oju rẹ, imu tabi ẹnu rẹ. Nipasẹ bẹẹ kokoro arun yii lee wọ ara rẹ ki o si sọ ọ di alailera. Duro si ile rẹ bi o ba ṣakiyesi pe ara rẹ ko ya. Bi o ba ni iba, ikọ ati iṣoro lati mi, tete tọ awọn oniṣegun oyinbo lọ fun ayẹwo ati itọju. Pe wọn ni ile iwosan naa silẹ, ki wọn lee ti gbaradi de ọ. Oniruuru iroyin lo n lọ kaakiri lori ọna ti o lee gba dena arun yii ati ohun gbogbo ti o nilo lati mọ nipa COVID-19 ti a mọ si coronavirus. Ma si ṣe gbagbe lati maa tẹle awọnilana eto ilera tawọn alaṣẹ ijọba lagbegbe rẹ ba fi sita. Awọn
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51670276
1entertainment
Orisabunmi: Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ ò! Lẹyìn ikú ẹ̀gbọ́n Orisabunmi, àbúrò rẹ̀ tún jáde láyé
Awọn mọlẹbi oserebinrin tiata Naijiria, Orisabunmi, ti tun wa ninu ẹkun ohun ibanujẹ ni kopẹ-kopẹ ti wọn padanu ẹgbọn Orisabunmi, iyẹn alagba Steve Onisola. Lọsan ọjọ Abamẹta ni arabinrin Bukola Janet Ademola, to jẹ aburo abikẹyin fun iya Orisabunmi naa jade laye. BBC Yoruba fidi ọrọ yi mulẹ lati ẹnu ọkan lara awọn to sunmọ arabinrin Bukola Janet, wolii ajihinrere Obaloluwa Hephzibah. Ninu alaye rẹ, Wolii Hephzibah ni ọdọ arabinrin Janet ni oun gbe dagba. Koda o sọ pe ọpọ eeyan lo maa n pe oun ni akọbi Janet Bukola. Hephzibah ni iku arabinrin Bukola Janet jẹ nkan ti o fọwọ kan ni lẹmi, to si ba ni lojiji pẹlu. ''Wọn ku lọsan ana. Ẹni to si ku lana yẹn lo tọ emi dagba. Ọdọ wọn ni mo gbe dagba. Aburo Orisabunmi ni wọn jẹ. Awọn ni abikẹyin mama to bi Orisabunmi." Nigba ti BBC Yoruba beere lọwọ Hephzibah nipa iroyin to n ja pe Covid-19 lo ṣokunfa iku arabinrin Bukola Janet, o ni awọn ko ro bẹẹ. ''Kii ṣe Corona. A le pe ni ''shock'' ati pe wọn ni Hypertension ti eleyi si n ba wọn finra tẹlẹ.'' Oniṣẹ aṣerun lọṣọ toloyinbo n pe ni Hairdresser ni arabinrin Janet Bukola jẹ nilu Ibadan. Ọjọ Kejila Osu Keji ọdun yii ni arabinrin Bukola Janet ko ba pe ẹni ọdun mẹtalelaadọta gẹgẹ bi Wolii Hephzibah ti ṣe sọ. Lakotan Hephzibah sọ fun BBC pe ilu Ibadan ṣi ni oku arabinrin Janet wa. "Ko ti daju igba ti wọn yoo sin nitori oku ti Oriṣabunmi to jẹ ẹgbọn ati ẹgbọn wọn agba, Steve Onisola ṣi wa nilẹ bayi, ti awọn mọlẹbi ko ti kede igba ti wọn yoo sin wọn." Lara awọn ẹbi to ṣẹku fun arabinrin Janet bayii ni ẹgbọn rẹ obinrin Alhaja Abiodun Dan Kazeem to jẹ iyawo sọrọ sọrọ Adeniyi Dan Kazeem. Saaju la ti sọ fun yin pe iroyin iku ẹni to jẹ ẹgbọn si gbajugbaja oṣere ere tiata Folake Aremu, Orisabunmi, ti desi eti igbọ wa. Ẹgbọn rẹ yi, Steve Onisola jẹ oludari ẹgbẹ agbabọọlu alapẹrẹ awọn obinrin ni Kwara,Kwara Falcons Basketball Club nigba aye rẹ. Alaga ẹgbẹ awọn to n gba bọọlu alapẹrẹ ni Kwara Dokita Joseph Adeyemo lo fidi ọrọ yi mulẹ fawọn akọroyin lọjọbọ. Gẹgẹ bi ohun taa gbọ, ko pe wakati mẹrinlelogun sigba ti Oriṣabunmi jade layi ti Onisola tii ṣe ẹni ọdun mọkanlelaadọrin ki duniya pe o digbere. Oniṣola ti fi igba orisirisi jẹ alakoso ẹgbẹ Falcons ki wọn to wa yan sipo oludari eto ẹgbẹ naa. O wa lara awọn to ṣapa ti ẹgbẹ naa fi gba agbega si abala liigi to gajulọ ni ọdun 2013. Bakan naa lo jẹ ọkan lara awọn to gba ami ẹyẹ fadaka nibi idije liigi Kwese lọdun 2018. Onisola jẹ ọkan lara awọn akọnimọọgba akọkọ ẹgbẹ naa ti wn da silẹ laarin ọdun 1970-80 O tun jẹ ọmọ ẹgbẹ igbimọ bọọlu alapẹrẹ ni ipinlẹ Kwara ṣaaju iku rẹ. Adeyemọ ṣapejuwe iku rẹ gẹg bi eyi to fọwọkan ẹmi awọn elere idaraya ati mọlẹbi rẹ nipinlẹ Kwara.
Orisabunmi: Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ ò! Lẹyìn ikú ẹ̀gbọ́n Orisabunmi, àbúrò rẹ̀ tún jáde láyé Awọn mọlẹbi oserebinrin tiata Naijiria, Orisabunmi, ti tun wa ninu ẹkun ohun ibanujẹ ni kopẹ-kopẹ ti wọn padanu ẹgbọn Orisabunmi, iyẹn alagba Steve Onisola. Lọsan ọjọ Abamẹta ni arabinrin Bukola Janet Ademola, to jẹ aburo abikẹyin fun iya Orisabunmi naa jade laye. BBC Yoruba fidi ọrọ yi mulẹ lati ẹnu ọkan lara awọn to sunmọ arabinrin Bukola Janet, wolii ajihinrere Obaloluwa Hephzibah. Ninu alaye rẹ, Wolii Hephzibah ni ọdọ arabinrin Janet ni oun gbe dagba. Koda o sọ pe ọpọ eeyan lo maa n pe oun ni akọbi Janet Bukola. Hephzibah ni iku arabinrin Bukola Janet jẹ nkan ti o fọwọ kan ni lẹmi, to si ba ni lojiji pẹlu. ''Wọn ku lọsan ana. Ẹni to si ku lana yẹn lo tọ emi dagba. Ọdọ wọn ni mo gbe dagba. Aburo Orisabunmi ni wọn jẹ. Awọn ni abikẹyin mama to bi Orisabunmi." Nigba ti BBC Yoruba beere lọwọ Hephzibah nipa iroyin to n ja pe Covid-19 lo ṣokunfa iku arabinrin Bukola Janet, o ni awọn ko ro bẹẹ. ''Kii ṣe Corona. A le pe ni ''shock'' ati pe wọn ni Hypertension ti eleyi si n ba wọn finra tẹlẹ.'' Oniṣẹ aṣerun lọṣọ toloyinbo n pe ni Hairdresser ni arabinrin Janet Bukola jẹ nilu Ibadan. Ọjọ Kejila Osu Keji ọdun yii ni arabinrin Bukola Janet ko ba pe ẹni ọdun mẹtalelaadọta gẹgẹ bi Wolii Hephzibah ti ṣe sọ. Lakotan Hephzibah sọ fun BBC pe ilu Ibadan ṣi ni oku arabinrin Janet wa. "Ko ti daju igba ti wọn yoo sin nitori oku ti Oriṣabunmi to jẹ ẹgbọn ati ẹgbọn wọn agba, Steve Onisola ṣi wa nilẹ bayi, ti awọn mọlẹbi ko ti kede igba ti wọn yoo sin wọn." Lara awọn ẹbi to ṣẹku fun arabinrin Janet bayii ni ẹgbọn rẹ obinrin Alhaja Abiodun Dan Kazeem to jẹ iyawo sọrọ sọrọ Adeniyi Dan Kazeem. Saaju la ti sọ fun yin pe iroyin iku ẹni to jẹ ẹgbọn si gbajugbaja oṣere ere tiata Folake Aremu, Orisabunmi, ti desi eti igbọ wa. Ẹgbọn rẹ yi, Steve Onisola jẹ oludari ẹgbẹ agbabọọlu alapẹrẹ awọn obinrin ni Kwara,Kwara Falcons Basketball Club nigba aye rẹ. Alaga ẹgbẹ awọn to n gba bọọlu alapẹrẹ ni Kwara Dokita Joseph Adeyemo lo fidi ọrọ yi mulẹ fawọn akọroyin lọjọbọ. Gẹgẹ bi ohun taa gbọ, ko pe wakati mẹrinlelogun sigba ti Oriṣabunmi jade layi ti Onisola tii ṣe ẹni ọdun mọkanlelaadọrin ki duniya pe o digbere. Oniṣola ti fi igba orisirisi jẹ alakoso ẹgbẹ Falcons ki wọn to wa yan sipo oludari eto ẹgbẹ naa. O wa lara awọn to ṣapa ti ẹgbẹ naa fi gba agbega si abala liigi to gajulọ ni ọdun 2013. Bakan naa lo jẹ ọkan lara awọn to gba ami ẹyẹ fadaka nibi idije liigi Kwese lọdun 2018. Onisola jẹ ọkan lara awọn akọnimọọgba akọkọ ẹgbẹ naa ti wn da silẹ laarin ọdun 1970-80 O tun jẹ ọmọ ẹgbẹ igbimọ bọọlu alapẹrẹ ni ipinlẹ Kwara ṣaaju iku rẹ. Adeyemọ ṣapejuwe iku rẹ gẹg bi eyi to fọwọkan ẹmi awọn elere idaraya ati mọlẹbi rẹ nipinlẹ Kwara.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-55586821
2health
Risikat Ilorin blue eyes woman: Inú èmí àti Òbí mi dùn nígbà ti Risi bí ọmọ olójú búlù àmọ́ ... - Wasiu
Mo fẹ ki Risikat pada sile ọdọ mi ni- Wasiu ọkọ Risikat "Mo fi Àlìkùrání búra pé mò ń tọ́jú Risikat àti àwọn ọmọ mi- Bàbá àwọn ọmọ olójú búlúù Wasiu to jẹ ọkọ Risikat oloju buluu ba BBC Yoruba sọrọ ni kikun lori ohun to ṣẹlẹ ki Risikat to ko lọ ati lẹyin to kuro nile rẹ. O ni o ba oun ninu jẹ lati gbọ irọ ti wọn n pa mọ oun pe oun le Risikat nile nitoripe o loju buluu. O sọrọ nipa awọn owo ti ohun ti na lori oju iyawo rẹ ati awọn ọmọ rẹ mejeeji. Koda, O fi Alkurani bura pe oun n ṣe ẹtọ to yẹ lori wọn. Risikat naa fidiẹ mulẹ pe nitootọ ni Wasiu ko le oun nile ṣugbọn iwa rẹ fihan pe ki oun ba ẹsẹ oun sọrọ nigba naa. O fi ẹsun kan awọn Obi Wasiu pe wọn maa n sọrọ nitori awọ buluu oju oun ati tọmọ ṣugbọn Wasiu ni irọ ni pe inu Obi oun dun si awọ oju rọ. Ile Olọmọyọyọ to jẹ agboole wọn ni BBC Yoruba lọ lati rii wọn ki a si mu oju aje kọ onisọ lati mọ okodoro ohun to ṣẹlẹ gangan Iya ati Baba Risikat naa sọ iha ti wọn kọ si ohun to ṣẹlẹ. Wasiu Jimoh ni oun diidi gbadura fun Risikat lati bi ọmọ oloju buluu ni ki awọn to bimọ ati pe oju yii ni Risikat fi n wu oun. O ni oun fẹ ki Risikat ko pada wa sile ṣugbọn kii ṣe nitori owo ti o ti pa lọwọ awọn eeyan rara.
Risikat Ilorin blue eyes woman: Inú èmí àti Òbí mi dùn nígbà ti Risi bí ọmọ olójú búlù àmọ́ ... - Wasiu Mo fẹ ki Risikat pada sile ọdọ mi ni- Wasiu ọkọ Risikat "Mo fi Àlìkùrání búra pé mò ń tọ́jú Risikat àti àwọn ọmọ mi- Bàbá àwọn ọmọ olójú búlúù Wasiu to jẹ ọkọ Risikat oloju buluu ba BBC Yoruba sọrọ ni kikun lori ohun to ṣẹlẹ ki Risikat to ko lọ ati lẹyin to kuro nile rẹ. O ni o ba oun ninu jẹ lati gbọ irọ ti wọn n pa mọ oun pe oun le Risikat nile nitoripe o loju buluu. O sọrọ nipa awọn owo ti ohun ti na lori oju iyawo rẹ ati awọn ọmọ rẹ mejeeji. Koda, O fi Alkurani bura pe oun n ṣe ẹtọ to yẹ lori wọn. Risikat naa fidiẹ mulẹ pe nitootọ ni Wasiu ko le oun nile ṣugbọn iwa rẹ fihan pe ki oun ba ẹsẹ oun sọrọ nigba naa. O fi ẹsun kan awọn Obi Wasiu pe wọn maa n sọrọ nitori awọ buluu oju oun ati tọmọ ṣugbọn Wasiu ni irọ ni pe inu Obi oun dun si awọ oju rọ. Ile Olọmọyọyọ to jẹ agboole wọn ni BBC Yoruba lọ lati rii wọn ki a si mu oju aje kọ onisọ lati mọ okodoro ohun to ṣẹlẹ gangan Iya ati Baba Risikat naa sọ iha ti wọn kọ si ohun to ṣẹlẹ. Wasiu Jimoh ni oun diidi gbadura fun Risikat lati bi ọmọ oloju buluu ni ki awọn to bimọ ati pe oju yii ni Risikat fi n wu oun. O ni oun fẹ ki Risikat ko pada wa sile ṣugbọn kii ṣe nitori owo ti o ti pa lọwọ awọn eeyan rara.
https://www.bbc.com/yoruba/53775777
1entertainment
Testimony Jaga: Ṣé èmi ọmọ alágbàdo, ọmọ orí títì ni ẹ̀mí ń lò báyìí?
A fẹrẹẹ ma le pe e ni olorin to ṣẹṣẹ n yọri soke mọ tori ọna ti orin rẹ gba jale jako ko ye ni mọ. A fi bii ina to n ran to si ti n sare burẹkẹ. Eyi ṣeese ko jẹ pe iru ohun ti awọn eeyan n fẹ ni awọn orin to n gbe jade. Olorin ẹmi ni awọn kan n pe e ti awọn mii si pin in si isọri olorin Fuji tabi takasufe. Jaga jẹ ọkan lara awọn to ti tan ina sinu agbo orin Kristẹni lọdun 2019 yii. Ara ọtọ ni orin rẹ to si ni imisi ninu pẹlu ọna ti o maa n gba gbe e jade. Bi ifede ti ẹmi fọ eyi to maa n waye laarin awọn Kristẹni ni orin rẹ ṣe maa n ri tabi ka tun juwe rẹ bi ẹni to n fa aaya eleyi ti awọn ijọ alaṣọ funfun maa n saba ṣe. Nigba kuugba ti Mr Jaga ba ti n ṣe eyi, o sọ fun BBC yoruba wi pe ẹmi Ọlọrun maa n sọkalẹ sara oun ti yoo si tun ba le awọn to ba wa ni ipejọpọ naa. "Mo ṣì ń gba ìpé lórí ìjẹ́rìí àwọn èèyàn tó ń gbọ́ orin mi. Ko ye emi naa bo ṣe n ṣẹlẹ, mi ò mọ bó ṣe ń ṣe mí mọ́, agbára Ọlọ̀run yẹn pọ̀ gan lára mi". Ọmọ ijọ nla nni, Christ Embassy nii ṣe eyi ti Pasitọ Chris Oyakhilome jẹ oludasilẹ rẹ. Ogbeni Jaga sọ pe nigbakuugba ti oun ba n kọ orin, Pasitọ Oyakhilome gan an kii le jokoo tori agbara ẹmi mimọ to n ri.
Testimony Jaga: Ṣé èmi ọmọ alágbàdo, ọmọ orí títì ni ẹ̀mí ń lò báyìí? A fẹrẹẹ ma le pe e ni olorin to ṣẹṣẹ n yọri soke mọ tori ọna ti orin rẹ gba jale jako ko ye ni mọ. A fi bii ina to n ran to si ti n sare burẹkẹ. Eyi ṣeese ko jẹ pe iru ohun ti awọn eeyan n fẹ ni awọn orin to n gbe jade. Olorin ẹmi ni awọn kan n pe e ti awọn mii si pin in si isọri olorin Fuji tabi takasufe. Jaga jẹ ọkan lara awọn to ti tan ina sinu agbo orin Kristẹni lọdun 2019 yii. Ara ọtọ ni orin rẹ to si ni imisi ninu pẹlu ọna ti o maa n gba gbe e jade. Bi ifede ti ẹmi fọ eyi to maa n waye laarin awọn Kristẹni ni orin rẹ ṣe maa n ri tabi ka tun juwe rẹ bi ẹni to n fa aaya eleyi ti awọn ijọ alaṣọ funfun maa n saba ṣe. Nigba kuugba ti Mr Jaga ba ti n ṣe eyi, o sọ fun BBC yoruba wi pe ẹmi Ọlọrun maa n sọkalẹ sara oun ti yoo si tun ba le awọn to ba wa ni ipejọpọ naa. "Mo ṣì ń gba ìpé lórí ìjẹ́rìí àwọn èèyàn tó ń gbọ́ orin mi. Ko ye emi naa bo ṣe n ṣẹlẹ, mi ò mọ bó ṣe ń ṣe mí mọ́, agbára Ọlọ̀run yẹn pọ̀ gan lára mi". Ọmọ ijọ nla nni, Christ Embassy nii ṣe eyi ti Pasitọ Chris Oyakhilome jẹ oludasilẹ rẹ. Ogbeni Jaga sọ pe nigbakuugba ti oun ba n kọ orin, Pasitọ Oyakhilome gan an kii le jokoo tori agbara ẹmi mimọ to n ri.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-50883692
1entertainment
Baba Ijesha: Ta ló yọ ojú òpó 'GoFundMe' tí wọ́n ṣí fún afurasí Olanrewaju Omiyinka kúrò lórí ayélujára?
Wọn ti yọ oju opo GoFundMe ti ẹnikan ṣi fun Baba Ijesha lati ba kowojọ lori igbẹjọ ifipa ba ọmọde lopọ kuro lori ayelujara. Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le sọ ni pato boya ọgbẹni Oladele Matti to ṣi oju opo naa lo yọ ni tabi ileeṣẹ GoFundMe funra rẹ. Ṣugbọn iroyin sọ pe igbeṣe naa waye lẹyin ti awọn eeyan kan bẹrẹ si n ṣe ifẹhonuhan lori ayelujara lẹyin ti Matti ṣi oju opo naa tan. Ṣaaju ni ni wọn ti kọkọ fẹsun kan Baba Ijesha pe o ba ọmọde ni ibalopọ lọna ti ko tọ, eyii to lodi si abala ofin 135, 137, 261, 202, 262 ati 263 to rọ mọ ibalopọ ni ipinlẹ Eko. Asiko ti igbẹjọ naa bẹrẹ ni ọkan lara awọn ololufẹ rẹ to fi orilẹ-ede Ireland ṣebugbe, Oladele Matti ṣi oju opo GoFundMe fun Baba Ijesha pẹlu erongba lati ko €50,000 jọ ko le fi ṣe ẹjọ ọhun. Nigba to n sọrọ lori idi to fi gbe igbeṣe naa, Matti ni "Mo n ṣe ikowojọ yii lati ran Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha lọwọ lori igbejọ rẹ." "Afojusun mi ni ki Baba Ijesha le ri idajọ ododo gba lori ẹsun ti wọn fi kan an." Ẹwẹ, igbesẹ naa ko dun mọ awọn kan ninu, ti wọn si woye eredi ti ẹnikan yoo fi gbiyanju lati ko owo jọ fun ẹni ti wọn fi ẹsun biba ọmọde lopọ kan. Lasiko ti BBC Yoruba ṣe abẹwo si oju opo naa, a ri wi pe ko si nibẹ mọ pẹlu akọle pe "A ko ri oju opo yi ṣi mọ." Ileeṣẹ GoFundMe jẹ ileeṣẹ kan to n fun awọn eeyan lanfani kaakiri agbaye lati ṣe ikowojọ fun eredi kan tabi omiran.
Baba Ijesha: Ta ló yọ ojú òpó 'GoFundMe' tí wọ́n ṣí fún afurasí Olanrewaju Omiyinka kúrò lórí ayélujára? Wọn ti yọ oju opo GoFundMe ti ẹnikan ṣi fun Baba Ijesha lati ba kowojọ lori igbẹjọ ifipa ba ọmọde lopọ kuro lori ayelujara. Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le sọ ni pato boya ọgbẹni Oladele Matti to ṣi oju opo naa lo yọ ni tabi ileeṣẹ GoFundMe funra rẹ. Ṣugbọn iroyin sọ pe igbeṣe naa waye lẹyin ti awọn eeyan kan bẹrẹ si n ṣe ifẹhonuhan lori ayelujara lẹyin ti Matti ṣi oju opo naa tan. Ṣaaju ni ni wọn ti kọkọ fẹsun kan Baba Ijesha pe o ba ọmọde ni ibalopọ lọna ti ko tọ, eyii to lodi si abala ofin 135, 137, 261, 202, 262 ati 263 to rọ mọ ibalopọ ni ipinlẹ Eko. Asiko ti igbẹjọ naa bẹrẹ ni ọkan lara awọn ololufẹ rẹ to fi orilẹ-ede Ireland ṣebugbe, Oladele Matti ṣi oju opo GoFundMe fun Baba Ijesha pẹlu erongba lati ko €50,000 jọ ko le fi ṣe ẹjọ ọhun. Nigba to n sọrọ lori idi to fi gbe igbeṣe naa, Matti ni "Mo n ṣe ikowojọ yii lati ran Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha lọwọ lori igbejọ rẹ." "Afojusun mi ni ki Baba Ijesha le ri idajọ ododo gba lori ẹsun ti wọn fi kan an." Ẹwẹ, igbesẹ naa ko dun mọ awọn kan ninu, ti wọn si woye eredi ti ẹnikan yoo fi gbiyanju lati ko owo jọ fun ẹni ti wọn fi ẹsun biba ọmọde lopọ kan. Lasiko ti BBC Yoruba ṣe abẹwo si oju opo naa, a ri wi pe ko si nibẹ mọ pẹlu akọle pe "A ko ri oju opo yi ṣi mọ." Ileeṣẹ GoFundMe jẹ ileeṣẹ kan to n fun awọn eeyan lanfani kaakiri agbaye lati ṣe ikowojọ fun eredi kan tabi omiran.
https://www.bbc.com/yoruba/media-57816092
2health
Queen Ereba Psoriasis: Níṣe ló dàbíi pé mo wà nínú àhámọ́ tí mi ò ṣẹ̀dá fúnra mi
Ṣe lo kan dede bẹrẹ si ni ri nkan kurukuru lara rẹ. Amọ ko si bi wọn ṣe lo gbogbo ipara ati ogun apakokoro ara to wa ni Naijiria to, ko ran an. Igba yẹn gaan lo ṣẹṣẹ wa mọ pe o ju agbara oun lọ. Àfi ṣuuuu ti gbogbo ẹ bo ara rẹ latori de ọmọ ika ẹsẹ. Aarun ipẹpẹ gbigbẹ lara eyi ti awọn dokita pe ni Psoriasis lo kọlu Queen Ereba. Eyi si fa irẹwẹsi si aye rẹ tori ko si agọ ara rẹ kankan ti aarun yii ko lẹ mọ. Bíbéèrè ìbálòpọ̀ láti ṣe ìwé ìrìnà sọ òṣìṣẹ́ iléèṣẹ́ ọmọ Nàìjíríà dèrò ilé O ro pe o ti tan fun oun laye koda wipe ala oun ko lee laye di mimuṣẹ. Ko lee ṣe ohun gbogbo bo ṣe wu u, ko lee wọ iru aṣọ to ba yan laayo lati wọ. Koda o ni lati pa ileewe ti nigba kan nitori aisan yii. Queen Ereba pada di onkọwe ati ololufẹ ohun meremere. Nibi ti aarun yii ba a finra de, o ti ṣe iwe jade ti akọle rẹ n jẹ "Psoriasi, finding your light". Wo ìdí tí akẹ́kọ̀ọ́jáde 96 kò fi ní leè ṣe àgùnbánirọ̀ wọn l'Ogun Àwọn oniròyìn ló tú àṣírí ààbò Prof Peller, tí wọn fi ri pa - Lady Peller
Queen Ereba Psoriasis: Níṣe ló dàbíi pé mo wà nínú àhámọ́ tí mi ò ṣẹ̀dá fúnra mi Ṣe lo kan dede bẹrẹ si ni ri nkan kurukuru lara rẹ. Amọ ko si bi wọn ṣe lo gbogbo ipara ati ogun apakokoro ara to wa ni Naijiria to, ko ran an. Igba yẹn gaan lo ṣẹṣẹ wa mọ pe o ju agbara oun lọ. Àfi ṣuuuu ti gbogbo ẹ bo ara rẹ latori de ọmọ ika ẹsẹ. Aarun ipẹpẹ gbigbẹ lara eyi ti awọn dokita pe ni Psoriasis lo kọlu Queen Ereba. Eyi si fa irẹwẹsi si aye rẹ tori ko si agọ ara rẹ kankan ti aarun yii ko lẹ mọ. Bíbéèrè ìbálòpọ̀ láti ṣe ìwé ìrìnà sọ òṣìṣẹ́ iléèṣẹ́ ọmọ Nàìjíríà dèrò ilé O ro pe o ti tan fun oun laye koda wipe ala oun ko lee laye di mimuṣẹ. Ko lee ṣe ohun gbogbo bo ṣe wu u, ko lee wọ iru aṣọ to ba yan laayo lati wọ. Koda o ni lati pa ileewe ti nigba kan nitori aisan yii. Queen Ereba pada di onkọwe ati ololufẹ ohun meremere. Nibi ti aarun yii ba a finra de, o ti ṣe iwe jade ti akọle rẹ n jẹ "Psoriasi, finding your light". Wo ìdí tí akẹ́kọ̀ọ́jáde 96 kò fi ní leè ṣe àgùnbánirọ̀ wọn l'Ogun Àwọn oniròyìn ló tú àṣírí ààbò Prof Peller, tí wọn fi ri pa - Lady Peller
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-54983384
4religion
RCCG: Àwọn Pásítọ́ ijọ Redeem márùn ún bọ́ sọ́wọ́ ajínigbé ní Ijebu Ode
Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, M.A Adamu ti pasẹ pe ki wọn se awari awọn eeyan to ji awọn pasitọ marun ti ijọ Redeem gbe. Atẹjade kan ti osisẹ alarina agba fun ileesẹ ọlọpa ilẹ wa, Frank Mba fisita ni ọjọ Ẹti salaye pe gbogbo ẹnu ni ọga agba ọlspa ilẹ yii fi koro oju sawọn isẹlẹ eto aabo to mẹhẹ to n waye lorilẹede yii. Bakan naa ni ọga agba ọlọpa tun pasẹ fun Kọmisana ọlọpa nipinlẹ Ogun pe awari ti obinrin n wa nkan ọbẹ ni ko fi ọrọ awọn pasitọ naa se, nipa dida awọn agbofinro sigboro lati wa awọn ajinigbe to sisẹ ibi ọhun. Osere tiata naa, ti oju rẹ ti gun rege pada ni "Mo fẹ lo akoko yii lati dupẹ pupọ lọwọ awọ Ko tan sibẹ, ọga agba ọlọpa naa tun ni wọn gbọdọ se awari awọn olubi ẹda to seku pa Fada kan fun ijọ Aguda, Ẹni ọwọ Paul Offu ni ipinlẹ Enugu. Bakan naa lo tun sọ fun kọmisana ọlọpa nipinlẹ Enugu lati da awọn ọlọpa sita, ki wọn lee tete mọ awọn eeyan to sisẹ ibi naa. Ìròyìn tó tẹ̀ wa lọ́wọ́ ní wí pé àwọn ajínigbé ti gbé òṣìṣẹ́ ìjọ àti Pásítọ̀ ìjọ The Redeem Christian Church of God, tí gbogbo wọ́n jẹ́ márùn ún gbé ní ìlú Ijebu Ode. Ìròyìn náà sọ wí pé lójúnà ìrìnàjò wọn lọ síbi ìpàdé àdùrà níbi ìpàgọ́ ńlá ti RCCG fún oṣu kẹjọ ni wọn ti bọ́ sí páńpẹ́ ajínigbé. Akọroyin wa kan si ọkan lara awọn Pásítọ̀ tó ti gúnlẹ̀ síbi ètò náà, ó sì fi àrídájú hàn pé lóòtọ́ ni tórí adarí ìjọ náà, Pásítọ̀ Enoch Adeboye fúnra rẹ̀ sọ ọ́ lásìkò ìsìn kan lówùrọ̀ yìí, wọ́n sì ti pa ohùn pọ̀ gbàdúrà fún ìtúsílẹ̀ wọn. Ọdọọdún ni ìpàgọ́ fún ìpàdé àdúrà náà máa ń wáyé èyí tó ma ń kó gbogbo ọmọ ìjọ papọ̀ káàkiri àgbáyé.
RCCG: Àwọn Pásítọ́ ijọ Redeem márùn ún bọ́ sọ́wọ́ ajínigbé ní Ijebu Ode Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, M.A Adamu ti pasẹ pe ki wọn se awari awọn eeyan to ji awọn pasitọ marun ti ijọ Redeem gbe. Atẹjade kan ti osisẹ alarina agba fun ileesẹ ọlọpa ilẹ wa, Frank Mba fisita ni ọjọ Ẹti salaye pe gbogbo ẹnu ni ọga agba ọlspa ilẹ yii fi koro oju sawọn isẹlẹ eto aabo to mẹhẹ to n waye lorilẹede yii. Bakan naa ni ọga agba ọlọpa tun pasẹ fun Kọmisana ọlọpa nipinlẹ Ogun pe awari ti obinrin n wa nkan ọbẹ ni ko fi ọrọ awọn pasitọ naa se, nipa dida awọn agbofinro sigboro lati wa awọn ajinigbe to sisẹ ibi ọhun. Osere tiata naa, ti oju rẹ ti gun rege pada ni "Mo fẹ lo akoko yii lati dupẹ pupọ lọwọ awọ Ko tan sibẹ, ọga agba ọlọpa naa tun ni wọn gbọdọ se awari awọn olubi ẹda to seku pa Fada kan fun ijọ Aguda, Ẹni ọwọ Paul Offu ni ipinlẹ Enugu. Bakan naa lo tun sọ fun kọmisana ọlọpa nipinlẹ Enugu lati da awọn ọlọpa sita, ki wọn lee tete mọ awọn eeyan to sisẹ ibi naa. Ìròyìn tó tẹ̀ wa lọ́wọ́ ní wí pé àwọn ajínigbé ti gbé òṣìṣẹ́ ìjọ àti Pásítọ̀ ìjọ The Redeem Christian Church of God, tí gbogbo wọ́n jẹ́ márùn ún gbé ní ìlú Ijebu Ode. Ìròyìn náà sọ wí pé lójúnà ìrìnàjò wọn lọ síbi ìpàdé àdùrà níbi ìpàgọ́ ńlá ti RCCG fún oṣu kẹjọ ni wọn ti bọ́ sí páńpẹ́ ajínigbé. Akọroyin wa kan si ọkan lara awọn Pásítọ̀ tó ti gúnlẹ̀ síbi ètò náà, ó sì fi àrídájú hàn pé lóòtọ́ ni tórí adarí ìjọ náà, Pásítọ̀ Enoch Adeboye fúnra rẹ̀ sọ ọ́ lásìkò ìsìn kan lówùrọ̀ yìí, wọ́n sì ti pa ohùn pọ̀ gbàdúrà fún ìtúsílẹ̀ wọn. Ọdọọdún ni ìpàgọ́ fún ìpàdé àdúrà náà máa ń wáyé èyí tó ma ń kó gbogbo ọmọ ìjọ papọ̀ káàkiri àgbáyé.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49202768
3politics
Kò bá à jẹ́ Tinubu tàbí Obi, à ní kí ipò ààrẹ bọ́ sẹ́kún gúúsù ló jà jù - Akeredolu
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kede pe oun ko ti yii ipinu oun pada lori pe ki ipo Aarẹ bọ si ẹkun guusu Naijiria. Akeredolu fi ọwọ idaniloju yii sọya nigba to sọrọ nibi ayẹyẹ iranti ọdun kan Ọjọgbọn Bankole Oke to waye ni fasiti ibadan lọjọbo. Akeredolu ni yoo dara ki ipo agbara bọ si ẹkun guusu orilẹede yii, ti oun ko si kọ boya o bọ si ọwọ Peter Obi ti Labour Party tabi Bola Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu APC. Akeredolu ni ilana ti wa lati ọdun 1999 pe agbara yoo maa yipo lati ẹkun ariwa si guusu Naijiria. Amọ o ni o ba oun ninu jẹ pe awọn kan lati ẹkun ariwa si fẹ gba agbara lọwọ Aarẹ Buhari. “Ti Peter Obi ba jẹ Aarẹ, o dara, ti Bola Ahmed Tinubu ba di Aarẹ, eyun naa dara, temi ni pe ki o jẹ pe a yan aarẹ tuntun lati ẹkun guusu orilẹede yii.” Akeredolu wa rọ awọn ọmọ orilẹede yii lati mase jẹ ki agbara pada si ẹkun ariwa nitori pe yoo ba ilana to ti wa lati ọdun 1999 jẹ ni. Gomina Akeredolu wa tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ẹgbẹ oṣelu to ba mu oludije lati ẹkun ariwa lasiko yii ko nifẹ araalu rara. O ni Peter Obi ni ẹtọ si ipo Aarẹ nitori pe lati ẹkun guusu lo ti wa.” “A ti ṣetan lati fi gbogbo nnkan ti a ni lati ri daju pe agbara wa si ẹkun guusu orilẹede yii.” O salaye pe igbọraẹniye ti wa lati ọdun 1999 pe, ipo agbara yoo ma lọ yika laarin ẹkun guusu ati ariwa. Sugbọn o ni awọn eeyan kan lo ni erongba lati yii atunto naa danu. Akeredolu wa kesi awọn araalu lati yago fun irufẹ awọn eeyan naa nitori wọn n wa ohunkonu, papaa julọ ọrọ ẹsin  lati fi tu Najiria ka. “Awọn eeyan yii fẹ da orilẹede Naijiria ru ni pẹlu erongba wọn ti ko ba ojumu, ti wọn si n wa gbogbo ọna lati ripe wọn wa ni ipo agbara. “A ko gbọdọ jẹ ki wọn fi ọrọ ẹsin tan wa, nitori kii ṣe ọrọ ẹsin lo kan, ninu gbogbo nnkan to n ba orilẹede yii finra.”
Kò bá à jẹ́ Tinubu tàbí Obi, à ní kí ipò ààrẹ bọ́ sẹ́kún gúúsù ló jà jù - Akeredolu Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kede pe oun ko ti yii ipinu oun pada lori pe ki ipo Aarẹ bọ si ẹkun guusu Naijiria. Akeredolu fi ọwọ idaniloju yii sọya nigba to sọrọ nibi ayẹyẹ iranti ọdun kan Ọjọgbọn Bankole Oke to waye ni fasiti ibadan lọjọbo. Akeredolu ni yoo dara ki ipo agbara bọ si ẹkun guusu orilẹede yii, ti oun ko si kọ boya o bọ si ọwọ Peter Obi ti Labour Party tabi Bola Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu APC. Akeredolu ni ilana ti wa lati ọdun 1999 pe agbara yoo maa yipo lati ẹkun ariwa si guusu Naijiria. Amọ o ni o ba oun ninu jẹ pe awọn kan lati ẹkun ariwa si fẹ gba agbara lọwọ Aarẹ Buhari. “Ti Peter Obi ba jẹ Aarẹ, o dara, ti Bola Ahmed Tinubu ba di Aarẹ, eyun naa dara, temi ni pe ki o jẹ pe a yan aarẹ tuntun lati ẹkun guusu orilẹede yii.” Akeredolu wa rọ awọn ọmọ orilẹede yii lati mase jẹ ki agbara pada si ẹkun ariwa nitori pe yoo ba ilana to ti wa lati ọdun 1999 jẹ ni. Gomina Akeredolu wa tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ẹgbẹ oṣelu to ba mu oludije lati ẹkun ariwa lasiko yii ko nifẹ araalu rara. O ni Peter Obi ni ẹtọ si ipo Aarẹ nitori pe lati ẹkun guusu lo ti wa.” “A ti ṣetan lati fi gbogbo nnkan ti a ni lati ri daju pe agbara wa si ẹkun guusu orilẹede yii.” O salaye pe igbọraẹniye ti wa lati ọdun 1999 pe, ipo agbara yoo ma lọ yika laarin ẹkun guusu ati ariwa. Sugbọn o ni awọn eeyan kan lo ni erongba lati yii atunto naa danu. Akeredolu wa kesi awọn araalu lati yago fun irufẹ awọn eeyan naa nitori wọn n wa ohunkonu, papaa julọ ọrọ ẹsin  lati fi tu Najiria ka. “Awọn eeyan yii fẹ da orilẹede Naijiria ru ni pẹlu erongba wọn ti ko ba ojumu, ti wọn si n wa gbogbo ọna lati ripe wọn wa ni ipo agbara. “A ko gbọdọ jẹ ki wọn fi ọrọ ẹsin tan wa, nitori kii ṣe ọrọ ẹsin lo kan, ninu gbogbo nnkan to n ba orilẹede yii finra.”
https://www.bbc.com/yoruba/articles/ce9nk940z73o
5sports
World Cup qualifier: Senegal àti Egypt yóò wáàkò fún tíkẹ́ẹ̀tì ife ẹ̀yẹ àgbáyé Qatar 2022
Ẹgbẹ agbabọọlu Senegal ati Egypt ni yoo koju ara awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye ni Qatar lọdun 2022 yii. Eyi tumọ si pe Mohamed Salah ati Sadio Mane ti wọn jọ jẹ ọmọ agbabọọlu Livrepool yoo koju ara wọn. Ikọ Super Eagles Naijiria yoo koju Black Stars Ghana ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye ni Qatar lọdun 2022 yii. Lonii ọjọ Abamẹta niluu Douala ni Cameroon wọn kede bi awọn ifẹsẹwọnsẹ naa yoo ṣe lọ nilẹ Afirika. Laarin ọjọ kọkanlelogun si ọjọ kọkandinlọgbọn ni ifẹsẹwọnsẹ mejeeji gbọdọ waye laarin Naijiria ati Ghana. Ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ mii, Mohamed Salah ati Sadio Mane yoo koju ara wọn nigba ti Egypt ati Senegal yoo maa waako. Cameroon to n gbalejo idije AFCON lọwọ yoo maa na tan bi owo pẹlu Algeria. Mali ati Tunisia yoo jọ maa ṣalaye fun ara wọn ẹni ti yoo lọ si idije ife ẹyẹ agbaye bi Qatar. Ikọ agbabọọlu DR Congo ati Morocco yoo jọ waako bakan naa.
World Cup qualifier: Senegal àti Egypt yóò wáàkò fún tíkẹ́ẹ̀tì ife ẹ̀yẹ àgbáyé Qatar 2022 Ẹgbẹ agbabọọlu Senegal ati Egypt ni yoo koju ara awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye ni Qatar lọdun 2022 yii. Eyi tumọ si pe Mohamed Salah ati Sadio Mane ti wọn jọ jẹ ọmọ agbabọọlu Livrepool yoo koju ara wọn. Ikọ Super Eagles Naijiria yoo koju Black Stars Ghana ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye ni Qatar lọdun 2022 yii. Lonii ọjọ Abamẹta niluu Douala ni Cameroon wọn kede bi awọn ifẹsẹwọnsẹ naa yoo ṣe lọ nilẹ Afirika. Laarin ọjọ kọkanlelogun si ọjọ kọkandinlọgbọn ni ifẹsẹwọnsẹ mejeeji gbọdọ waye laarin Naijiria ati Ghana. Ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ mii, Mohamed Salah ati Sadio Mane yoo koju ara wọn nigba ti Egypt ati Senegal yoo maa waako. Cameroon to n gbalejo idije AFCON lọwọ yoo maa na tan bi owo pẹlu Algeria. Mali ati Tunisia yoo jọ maa ṣalaye fun ara wọn ẹni ti yoo lọ si idije ife ẹyẹ agbaye bi Qatar. Ikọ agbabọọlu DR Congo ati Morocco yoo jọ waako bakan naa.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-60096976
3politics
Mo ní ìbọ̀wọ̀ fún ẹ̀sìn Kristẹ̀ní àmọ́ ìdí tí mo fí yan Mùsùlùmí gẹ́gẹ́ bí ìgbákèjì rèé – Tinubu
Oludije lẹgbẹ oṣelu APC fun ipo aarẹ, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti sọ pe oun ni ibọwọ to peye fun ẹsin mejeeji to tobi julọ ti wọn n ṣe lorilẹede Naijiria. Ahmed Tinubu sọ eyi lẹyin to yan gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ, Kashim Shettima gẹgẹ bi igbakeji oludije lẹgbẹ oṣelu APC. O ni yiyan ti oun yan an ko nii ṣe pẹlu pe oun ko bọwọ fun ẹsin Kristẹni, nitori oun bọwọ fun ẹsin naa ti oun ko si fi ọwọ rọọ si ẹyin. Bakan naa lo ni oun gbọ gbogbo ẹdun ọkan awọn ti ko lọwọ si yiyan ẹlẹsin musulumi gẹgẹ bi igbakeji amọ o ni ilọsiwaju orilẹede Niajiria lo pọn dandan. ‘’Gbogbo ẹyin ti inu yin ko dun si ẹni ti mo yan nitori ẹsin, ẹma binu amọ kii ṣe pe mi o kọ ibi ara si ẹsin Kristẹni.’’ ‘’Mi o ni lailai tabuku ẹsin kankan ni Naijiria nitori mọ mọ bi o ṣe ri lara awọn ọmọ Naijiria’’ ‘’Mo si fi iye si gbogbo ẹdun ọkan awọn ẹniyan lori yiyan ti mo yan igbakeji.’’ Amọ Tinubu ni ko gbọdọ maa lọ lailai ki oun gbogbo ti ijọba ba fẹ ṣe gbọdọ jẹ nipa ẹsin tabi ẹya. O ni ipenija orilẹede Niajiria lọwọlọwọ n beere fun ki awọn eniyan fi ọkan si ẹni to ba pegede ju ọrọ ẹsin lọ. Tinubu ni awọn ọmọ Naijiria gbọdọ bẹrẹ si ni fi oju si ẹni ti yoo mu idagbasoke ati aṣeyọri ba orilẹede Naijiria, kii ṣe ọrọ ẹsin. Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu, ti kede sẹnetọ Kashim Shetima, gẹgẹ bii igbakeji rẹ ti wọn yo jọ dije. Tinubu lo fi ikede yii sita lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Daura, tii ṣe ilu Aarẹ Muhammadu Buhari. Shetima ni gomina ipinlẹ Borno laarin ọdun 2011 si 2019. Ṣaaju ni Tinubu ti kọkọ ṣe ipade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ninu ile rẹ naa ni Daura fun nnkan bii wakati kan ko to jade lati fi ikede ọhun sita. Gẹgẹ bii ohun ti Tinubu sọ, o yan Shettima  nitori o jẹ ẹnikan to jafafa, to ṣe fọkan tan, ati ẹni to mọ ohun to n ṣe. Lara awọn to ba Tinubu lọ si Daura ni Gomina Aminu Masari lẹyin ti ọkọ ofurufu to gbe Tinubu balẹ si papakọ ofurufu ti Umaru Musa Yar’Adua ni Katsina. Nigba ti so n sọrọ lori ikede naa, minisita eto igbanisiṣẹ, Festus Keyamo, juwe Kashim Shettima gẹgẹ bii ẹni to tọ fun Tinubu lati yan gẹgẹ bii igbakeji rẹ. Ninu atẹjade kan to fi soju opo Twitter rẹ, Keyamo sọ pe Tinubu ko ṣe aṣiṣẹ nipa yiyan Shettima. O ni “Oṣiṣẹ ile ifowopamọsi to dantọ ati onimọ nipa eto ọrọ aje to ṣe mu yangan” ni Shettima. “Shettima gan ni ẹni to tọ fun Tinubu lati yan gẹgẹ bii igbakeji rẹ.” Ẹwẹ, ẹni ti wọn kọkọ yan lati ṣe igbakeji Tinubu, Ibrahim Masari ti ni oun ko ṣe mọ. Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Aiku, o ni lẹyin ijiroro pẹlu awọn ti ọrọ kan, oun ti jawọ ipo igbakeji naa. Lẹyin naa lo gbadura ki Ọlọrun jẹ ki ipo Aarẹ ti Tinubu n du bọ si lọwọ gẹgẹ bii ero ọkan rẹ.
Mo ní ìbọ̀wọ̀ fún ẹ̀sìn Kristẹ̀ní àmọ́ ìdí tí mo fí yan Mùsùlùmí gẹ́gẹ́ bí ìgbákèjì rèé – Tinubu Oludije lẹgbẹ oṣelu APC fun ipo aarẹ, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti sọ pe oun ni ibọwọ to peye fun ẹsin mejeeji to tobi julọ ti wọn n ṣe lorilẹede Naijiria. Ahmed Tinubu sọ eyi lẹyin to yan gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ, Kashim Shettima gẹgẹ bi igbakeji oludije lẹgbẹ oṣelu APC. O ni yiyan ti oun yan an ko nii ṣe pẹlu pe oun ko bọwọ fun ẹsin Kristẹni, nitori oun bọwọ fun ẹsin naa ti oun ko si fi ọwọ rọọ si ẹyin. Bakan naa lo ni oun gbọ gbogbo ẹdun ọkan awọn ti ko lọwọ si yiyan ẹlẹsin musulumi gẹgẹ bi igbakeji amọ o ni ilọsiwaju orilẹede Niajiria lo pọn dandan. ‘’Gbogbo ẹyin ti inu yin ko dun si ẹni ti mo yan nitori ẹsin, ẹma binu amọ kii ṣe pe mi o kọ ibi ara si ẹsin Kristẹni.’’ ‘’Mi o ni lailai tabuku ẹsin kankan ni Naijiria nitori mọ mọ bi o ṣe ri lara awọn ọmọ Naijiria’’ ‘’Mo si fi iye si gbogbo ẹdun ọkan awọn ẹniyan lori yiyan ti mo yan igbakeji.’’ Amọ Tinubu ni ko gbọdọ maa lọ lailai ki oun gbogbo ti ijọba ba fẹ ṣe gbọdọ jẹ nipa ẹsin tabi ẹya. O ni ipenija orilẹede Niajiria lọwọlọwọ n beere fun ki awọn eniyan fi ọkan si ẹni to ba pegede ju ọrọ ẹsin lọ. Tinubu ni awọn ọmọ Naijiria gbọdọ bẹrẹ si ni fi oju si ẹni ti yoo mu idagbasoke ati aṣeyọri ba orilẹede Naijiria, kii ṣe ọrọ ẹsin. Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu, ti kede sẹnetọ Kashim Shetima, gẹgẹ bii igbakeji rẹ ti wọn yo jọ dije. Tinubu lo fi ikede yii sita lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Daura, tii ṣe ilu Aarẹ Muhammadu Buhari. Shetima ni gomina ipinlẹ Borno laarin ọdun 2011 si 2019. Ṣaaju ni Tinubu ti kọkọ ṣe ipade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ninu ile rẹ naa ni Daura fun nnkan bii wakati kan ko to jade lati fi ikede ọhun sita. Gẹgẹ bii ohun ti Tinubu sọ, o yan Shettima  nitori o jẹ ẹnikan to jafafa, to ṣe fọkan tan, ati ẹni to mọ ohun to n ṣe. Lara awọn to ba Tinubu lọ si Daura ni Gomina Aminu Masari lẹyin ti ọkọ ofurufu to gbe Tinubu balẹ si papakọ ofurufu ti Umaru Musa Yar’Adua ni Katsina. Nigba ti so n sọrọ lori ikede naa, minisita eto igbanisiṣẹ, Festus Keyamo, juwe Kashim Shettima gẹgẹ bii ẹni to tọ fun Tinubu lati yan gẹgẹ bii igbakeji rẹ. Ninu atẹjade kan to fi soju opo Twitter rẹ, Keyamo sọ pe Tinubu ko ṣe aṣiṣẹ nipa yiyan Shettima. O ni “Oṣiṣẹ ile ifowopamọsi to dantọ ati onimọ nipa eto ọrọ aje to ṣe mu yangan” ni Shettima. “Shettima gan ni ẹni to tọ fun Tinubu lati yan gẹgẹ bii igbakeji rẹ.” Ẹwẹ, ẹni ti wọn kọkọ yan lati ṣe igbakeji Tinubu, Ibrahim Masari ti ni oun ko ṣe mọ. Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Aiku, o ni lẹyin ijiroro pẹlu awọn ti ọrọ kan, oun ti jawọ ipo igbakeji naa. Lẹyin naa lo gbadura ki Ọlọrun jẹ ki ipo Aarẹ ti Tinubu n du bọ si lọwọ gẹgẹ bii ero ọkan rẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cj7n4ymkpz2o
3politics
Ẹgbẹ́ APC ní láti wà lórí oyè kí ìjọba tiwantiwan lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa - Mai Mala Buni
Alaga ẹgbẹ oṣẹlu APC, to tun jẹ gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni ti sọ pe afojusun ẹgbẹ ọhun ni lati tukọ ijọba Naijiria fun ọdun mejilelọgbọn. Mai Mala lo sọ ọrọ naa lasiko to n yan igbimọ ẹlẹni mọkanlelọgọta kan ti yoo ṣeto apero ẹgbẹ ọhun to n bọ lọna ni ọọfisi ẹgbẹ naa to wa niluu Abuja. Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹgbẹ eṣelu APC ni lati wa lori ipo fun ọpọ ọdun ki ijọba tiwantiwa to ti bẹrẹ lati ọdun 2015 le fẹsẹ mulẹ daadaa. O ṣalaye pe awọn gbe igbimọ naa kalẹ ki wọn le mu ipinu naa ṣẹ. Lara awọn to wa ninu igbimọ ọhun ni awọn gomina, minisita, ṣenatọ atawọn agbagba oloṣelu, eyii ti gomina ipinlẹ Jigawa, Muhammadu Badaru Abubakar ṣe olori wọn. Lati igba ti wọn ti yan gomina ipinlẹ Yobe yii gẹgẹ bii alaga fidihẹ ẹgbẹ APC ni awọn awuyewuye kan ti n waye ninu ẹgbẹ naa. Ṣugbọn o ti n gbiyanju lati ri daju irẹpọ wa ninu ẹgbẹ ọhun.
Ẹgbẹ́ APC ní láti wà lórí oyè kí ìjọba tiwantiwan lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa - Mai Mala Buni Alaga ẹgbẹ oṣẹlu APC, to tun jẹ gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni ti sọ pe afojusun ẹgbẹ ọhun ni lati tukọ ijọba Naijiria fun ọdun mejilelọgbọn. Mai Mala lo sọ ọrọ naa lasiko to n yan igbimọ ẹlẹni mọkanlelọgọta kan ti yoo ṣeto apero ẹgbẹ ọhun to n bọ lọna ni ọọfisi ẹgbẹ naa to wa niluu Abuja. Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹgbẹ eṣelu APC ni lati wa lori ipo fun ọpọ ọdun ki ijọba tiwantiwa to ti bẹrẹ lati ọdun 2015 le fẹsẹ mulẹ daadaa. O ṣalaye pe awọn gbe igbimọ naa kalẹ ki wọn le mu ipinu naa ṣẹ. Lara awọn to wa ninu igbimọ ọhun ni awọn gomina, minisita, ṣenatọ atawọn agbagba oloṣelu, eyii ti gomina ipinlẹ Jigawa, Muhammadu Badaru Abubakar ṣe olori wọn. Lati igba ti wọn ti yan gomina ipinlẹ Yobe yii gẹgẹ bii alaga fidihẹ ẹgbẹ APC ni awọn awuyewuye kan ti n waye ninu ẹgbẹ naa. Ṣugbọn o ti n gbiyanju lati ri daju irẹpọ wa ninu ẹgbẹ ọhun.
https://www.bbc.com/yoruba/56501939
5sports
Wo ohun tí Mbeuno, atamátàsé Cameroun sọ nípa àǹfàní tó ní láti kópa ní ìdíje 'World cup'
Atamatase ẹgbẹ agbabọọlu Brentford, Bryan Mbeuno ti sọ pe idunu nlanla ni yoo jẹ fun oun bi oun ba lee bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ kankan fun orilẹede Cameroun ni idije ife ẹyẹ agbaye. Agbabọọlu ẹni ọdun mẹtalelogun naa wa lara awọn agbabọọlu ti wọn pe lati ṣoju Cameroun ni Qatar nibi ti wọn yoo ti maa koju Brazil, Serbia ati Switzerland. Mbeunmo sọ fun BBC Sport Africa pe, “O ti n wu mi lati igba ewe mi lati kopa ni idije agbaye. “Ki n kan maa rin kiri papa iṣire pẹlu ọpọ ero to n woran yoo fẹrẹ mu mi ya were.” Papa iṣire Al Janoub to gba ẹgbẹrun lọna ogoji ero iworan ati papa iṣire Lusai iconic stadium to gba ẹgbẹrun lọna ọgọrin ni Cameroun yoo ti gba ifẹsẹwọnsẹ wọn. Laipẹ yii ni Mbeuna yi oju pada lati bẹrẹ si ni ṣoju orilẹede Cameroun lẹyin to ti gba bọọlu fun ikọ agbabọọlu ọjẹ wẹwẹ orilẹede France ṣaaju. Ọmọ ilu Douala ni baba rẹ, nibẹ si tun ni ilu gbajumọ agbabọọlu ni Samuel Eto’o. Eto’o di alaga ajọ ere bọọlu Cameroun lọdun 2021. Kii ṣe ipa kekere ni Eto’o kan lati rii pe Mbeuno di agbabọọlu fun Cameroun. Mbeuno ni ipinnu to nira diẹ lo jẹ fun oun lati fi ta ilu iya oun nu lati wa gba bọọlu fun Cameroun. O ni oun mọ ikọ agbabọọlu Cameroun daadaa nitori pe nigba ewe loun ti maa n wo idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika, AFCON. “Nitori pe mio ti gba bọọlu fun ikọ ọjẹ wẹwẹ orilẹede France ri, ti mo si gbe ni France, O ṣoro pupọ ṣugbn mo ti wa si Cameroun lọpọ igba.” “Inu baba mi dun gidigidi. Inu mi dun lati kopa ninu eyi nitori baba mi, ati ẹbi mi. Inu baba mi si dun gidigidi.” Ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Uzbekistan ni Mbeuno ti kọkọ gba bọọlu fun Cameroun. Goolu meji sodo ni wọn si fi fidirẹmi ki South Korea to gbo ewuro si oju wọn pẹlu goolu kan si odo. “Awọn ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti mo kọkọ gba niyi, ẹkọ pupọ ni mo si kọ.” Bi o tilẹ jẹ wi pe orilẹede Cameroun ja fafa ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ to kọkọ gba ni idje ife ẹyẹ agbaye. Lọdun 1990 lo pegede gẹgẹ bi orilẹede akọkọ ni Afrika ti yoo wọ ipele quarter finals ni idije ife ẹyẹ agbaye. Amọṣa, lẹnu lọwọlọwọ yii, Cameroun ko ja fafa to bayi ni idije ife ẹyẹ agbaye. Lati ọdun 1994, ifẹsẹwọnsẹ marundinlogun ni Cameroun ti gba ni idije ife ẹyẹ agbaye, ẹyọ kan ṣoṣo pere ni wọn tii bori. Goolu kan ṣoṣo ni wọn fi bori Saudi Arabia, Samuel Eto’o lo gba goolu naa sinu awọn lọdun naa ni 2002. Ifẹsẹwọnsẹ mẹwaa ni wọn ti fidirẹmi ti wọn si gba ọgbọn goolu sinu awọn wọn. Cameroun yoo ṣi gba ifẹsẹwọnsẹ lọrẹsọrẹ kan pẹlu Panama lọjọ kejidinlogun oṣu kọkanla ọdun 2022 lati gbaradi fun idije ife ẹyẹ agbaye. Ipin G ni Cameroun wa, orilẹede Switzerland ni yoo koju lọjọ kẹrinlelogun oṣu kọkanla, ki wọn to koju Serbia ni ọjọ kejidinlọgbn oṣu kejila. Btazil ni wọn yoo koju gbẹyin ni ipin naa ni ọjọ keji oṣu kejila ọdun 2022.
Wo ohun tí Mbeuno, atamátàsé Cameroun sọ nípa àǹfàní tó ní láti kópa ní ìdíje 'World cup' Atamatase ẹgbẹ agbabọọlu Brentford, Bryan Mbeuno ti sọ pe idunu nlanla ni yoo jẹ fun oun bi oun ba lee bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ kankan fun orilẹede Cameroun ni idije ife ẹyẹ agbaye. Agbabọọlu ẹni ọdun mẹtalelogun naa wa lara awọn agbabọọlu ti wọn pe lati ṣoju Cameroun ni Qatar nibi ti wọn yoo ti maa koju Brazil, Serbia ati Switzerland. Mbeunmo sọ fun BBC Sport Africa pe, “O ti n wu mi lati igba ewe mi lati kopa ni idije agbaye. “Ki n kan maa rin kiri papa iṣire pẹlu ọpọ ero to n woran yoo fẹrẹ mu mi ya were.” Papa iṣire Al Janoub to gba ẹgbẹrun lọna ogoji ero iworan ati papa iṣire Lusai iconic stadium to gba ẹgbẹrun lọna ọgọrin ni Cameroun yoo ti gba ifẹsẹwọnsẹ wọn. Laipẹ yii ni Mbeuna yi oju pada lati bẹrẹ si ni ṣoju orilẹede Cameroun lẹyin to ti gba bọọlu fun ikọ agbabọọlu ọjẹ wẹwẹ orilẹede France ṣaaju. Ọmọ ilu Douala ni baba rẹ, nibẹ si tun ni ilu gbajumọ agbabọọlu ni Samuel Eto’o. Eto’o di alaga ajọ ere bọọlu Cameroun lọdun 2021. Kii ṣe ipa kekere ni Eto’o kan lati rii pe Mbeuno di agbabọọlu fun Cameroun. Mbeuno ni ipinnu to nira diẹ lo jẹ fun oun lati fi ta ilu iya oun nu lati wa gba bọọlu fun Cameroun. O ni oun mọ ikọ agbabọọlu Cameroun daadaa nitori pe nigba ewe loun ti maa n wo idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika, AFCON. “Nitori pe mio ti gba bọọlu fun ikọ ọjẹ wẹwẹ orilẹede France ri, ti mo si gbe ni France, O ṣoro pupọ ṣugbn mo ti wa si Cameroun lọpọ igba.” “Inu baba mi dun gidigidi. Inu mi dun lati kopa ninu eyi nitori baba mi, ati ẹbi mi. Inu baba mi si dun gidigidi.” Ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Uzbekistan ni Mbeuno ti kọkọ gba bọọlu fun Cameroun. Goolu meji sodo ni wọn si fi fidirẹmi ki South Korea to gbo ewuro si oju wọn pẹlu goolu kan si odo. “Awọn ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti mo kọkọ gba niyi, ẹkọ pupọ ni mo si kọ.” Bi o tilẹ jẹ wi pe orilẹede Cameroun ja fafa ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ to kọkọ gba ni idje ife ẹyẹ agbaye. Lọdun 1990 lo pegede gẹgẹ bi orilẹede akọkọ ni Afrika ti yoo wọ ipele quarter finals ni idije ife ẹyẹ agbaye. Amọṣa, lẹnu lọwọlọwọ yii, Cameroun ko ja fafa to bayi ni idije ife ẹyẹ agbaye. Lati ọdun 1994, ifẹsẹwọnsẹ marundinlogun ni Cameroun ti gba ni idije ife ẹyẹ agbaye, ẹyọ kan ṣoṣo pere ni wọn tii bori. Goolu kan ṣoṣo ni wọn fi bori Saudi Arabia, Samuel Eto’o lo gba goolu naa sinu awọn lọdun naa ni 2002. Ifẹsẹwọnsẹ mẹwaa ni wọn ti fidirẹmi ti wọn si gba ọgbọn goolu sinu awọn wọn. Cameroun yoo ṣi gba ifẹsẹwọnsẹ lọrẹsọrẹ kan pẹlu Panama lọjọ kejidinlogun oṣu kọkanla ọdun 2022 lati gbaradi fun idije ife ẹyẹ agbaye. Ipin G ni Cameroun wa, orilẹede Switzerland ni yoo koju lọjọ kẹrinlelogun oṣu kọkanla, ki wọn to koju Serbia ni ọjọ kejidinlọgbn oṣu kejila. Btazil ni wọn yoo koju gbẹyin ni ipin naa ni ọjọ keji oṣu kejila ọdun 2022.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c3g5xzrxv3vo
1entertainment
Africa in Pictures: Àwọn àwòràn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti ilẹ̀ Afirika
Awọn aworan yii lo n se afihan ọp isẹlẹ to waye laarin ọsẹ to n pari yii lati awọn orilẹede yika ilẹ Afirika.
Africa in Pictures: Àwọn àwòràn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti ilẹ̀ Afirika Awọn aworan yii lo n se afihan ọp isẹlẹ to waye laarin ọsẹ to n pari yii lati awọn orilẹede yika ilẹ Afirika.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49046362
1entertainment
Baba Ijesha: Ilẹẹjọ́ fagilé ẹ̀bẹ̀ Baba Ijesha tó ní pẹ̀lú ipá ni òun fi kọ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ ní àgọ́ ọlọ́pàá
Adajọ ileẹjo giga to wa ni Ikeja to n risi ọrọ ifipabinilopọ, Oluwatoyin Taiwo ti ko ọrọ Olanrewaju James ti ọpọ si Baba Ijesha danu pé òun kọ ni oun kọ gbogbo akọsilẹ ti ọlọpaa beere fun lọjọ ti wọn mu u.Adajọ Taiwo ni ẹ̀rí náà ko to nipa pe wọn na an àti pe ti wọn si fi tipatipa ni ko kọ ọrọ akọsilẹ.Ní ìtẹ̀síwájú igbẹjọ Baba Ijesha lórí ẹsun biba ọmọde lopọ ti wọn fi kan an, afurasi naa tún ti yọjú sílé ẹjọ lónìí lẹ́yìn ti awọn agbẹjọro rẹ̀ pe fun ki adajọ wọgile ọrọ akọsilẹ Ijesha nibi ẹjọ to oṣu to lọ nitori inu ira lo ti kọ ọrọ naa. Èmi àti ọmọ ẹgbẹ́ akọrin wa jọ yó ìfẹ́ ara wa ni - Pásítọ̀ ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìfipábáni lòpọ̀ Awọn olupẹjọ tun mu ẹlẹri wọn to jẹ ọlọpaa Abigael Onome wa si ileẹjọ lónìí lati tun wa ro tẹnu rẹ̀ leyii ti ọkan lara awọn agbẹjọrọ Ijesha Kayode Olabiran tun fọrọ wa a lẹnu wo ti awon olupẹjọ si sọ pé ẹlẹri awọn to kẹhin naa ni ọlọpaa ọhun.Ẹwè, nibi ti ẹjọ de duro bayii awọn olupẹjọ ti fi ẹjọ rọ̀ lati ọdọ wọn. Agbẹjọro Olabiran ṣalaye ileẹjọ pada gba oun ti Baba Ijesha kọ silẹ ni agọ ọlọpaa gẹgẹ ọkan lara awọn ẹri ipẹjọ. O ni oun adajọ sọ pe ko si ẹri to daju to le fidi rẹ mulẹ pe wọn lu Baba Ijesha ṣaaju akoko to kọ ọrọ rẹ silẹ. Olabiran ni adajọ tun sọ pe ọmọdebinrin ti wọn fẹsun kan Baba Ijesha pe o fipa ba lopọ gan an lo lu u. Agbẹjọro Olabiran wa fikun ọrọ rẹ pe Baba Ijesha lo ku bayii lati maa mu ẹri ijẹjọ wa ti igbẹjọ ba tun gberasọ lọdun to n bọ. Ileẹjọ sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu tó n bọ ọdun 2022.
Baba Ijesha: Ilẹẹjọ́ fagilé ẹ̀bẹ̀ Baba Ijesha tó ní pẹ̀lú ipá ni òun fi kọ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ ní àgọ́ ọlọ́pàá Adajọ ileẹjo giga to wa ni Ikeja to n risi ọrọ ifipabinilopọ, Oluwatoyin Taiwo ti ko ọrọ Olanrewaju James ti ọpọ si Baba Ijesha danu pé òun kọ ni oun kọ gbogbo akọsilẹ ti ọlọpaa beere fun lọjọ ti wọn mu u.Adajọ Taiwo ni ẹ̀rí náà ko to nipa pe wọn na an àti pe ti wọn si fi tipatipa ni ko kọ ọrọ akọsilẹ.Ní ìtẹ̀síwájú igbẹjọ Baba Ijesha lórí ẹsun biba ọmọde lopọ ti wọn fi kan an, afurasi naa tún ti yọjú sílé ẹjọ lónìí lẹ́yìn ti awọn agbẹjọro rẹ̀ pe fun ki adajọ wọgile ọrọ akọsilẹ Ijesha nibi ẹjọ to oṣu to lọ nitori inu ira lo ti kọ ọrọ naa. Èmi àti ọmọ ẹgbẹ́ akọrin wa jọ yó ìfẹ́ ara wa ni - Pásítọ̀ ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìfipábáni lòpọ̀ Awọn olupẹjọ tun mu ẹlẹri wọn to jẹ ọlọpaa Abigael Onome wa si ileẹjọ lónìí lati tun wa ro tẹnu rẹ̀ leyii ti ọkan lara awọn agbẹjọrọ Ijesha Kayode Olabiran tun fọrọ wa a lẹnu wo ti awon olupẹjọ si sọ pé ẹlẹri awọn to kẹhin naa ni ọlọpaa ọhun.Ẹwè, nibi ti ẹjọ de duro bayii awọn olupẹjọ ti fi ẹjọ rọ̀ lati ọdọ wọn. Agbẹjọro Olabiran ṣalaye ileẹjọ pada gba oun ti Baba Ijesha kọ silẹ ni agọ ọlọpaa gẹgẹ ọkan lara awọn ẹri ipẹjọ. O ni oun adajọ sọ pe ko si ẹri to daju to le fidi rẹ mulẹ pe wọn lu Baba Ijesha ṣaaju akoko to kọ ọrọ rẹ silẹ. Olabiran ni adajọ tun sọ pe ọmọdebinrin ti wọn fẹsun kan Baba Ijesha pe o fipa ba lopọ gan an lo lu u. Agbẹjọro Olabiran wa fikun ọrọ rẹ pe Baba Ijesha lo ku bayii lati maa mu ẹri ijẹjọ wa ti igbẹjọ ba tun gberasọ lọdun to n bọ. Ileẹjọ sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu tó n bọ ọdun 2022.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-59675112
4religion
Kano Marwa: Awakọ̀ kẹ̀kẹ́ Maruwa tó bá gbé okùnrin àti obìnrin ní Kano yóò jẹ palamba ìyà- Hisbah
Ijọba ipinlẹ Kano ti sọ pe, o ti di eewọ fun awakọ keke Maruwa lati gbe okunrin ati obinrin papọ nipinlẹ ọhun. Ajọ ọlọpaa Sharia ipinlẹ naa, Hisbah sọ pe, lati ọjọ keji oṣu, Kinni ọdun 2020, ẹnikẹni ti wọn ba gba mu pe o ru ofin naa yoo jẹ iyan rẹ niṣu. Adari ajọ naa, Sheik Harun Ibn-Sina fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC. O ni, ijiya fun ẹni to ba tapa si ofin naa ni pe wọn yoo gbẹsẹ le kẹkẹ rẹ fun oṣu mẹfa, tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun marun un naira ati bulala mẹwaa. Ibn-Sina ṣalaye pe "Ofin yii ti wa lati ọdun 2005, ṣugbọn a ṣẹṣẹ fẹ bẹrẹ si ni muu lo ni, ki a le fọ ipinlẹ wa mọ." O ni lati akoko yii di ipari ọdun, awakọ maruwa to ba gbe obinrin ati okunrin papọ yoo ni lati ja ero kan silẹ. Ṣugbọn lati ọjọ keji oṣu, Kinni ọdun 2020 ni ijiya ni pẹrẹu yoo bẹrẹ fun awọn to ba tapa sofin naa. Ibn-Sina ni awọn ẹṣọ ajọ ọhun ti gunlẹ si gbogbo ijọba ibilẹ mẹrinlelogoji to wa nipinlẹ Kano lati fẹsẹ ofin ọhun mulẹ. O ni tọkọtaya lee wọ keke kan naa papọ ti wọn ba lee bura pe awọn mejeji ti gbera wọn niyawo.
Kano Marwa: Awakọ̀ kẹ̀kẹ́ Maruwa tó bá gbé okùnrin àti obìnrin ní Kano yóò jẹ palamba ìyà- Hisbah Ijọba ipinlẹ Kano ti sọ pe, o ti di eewọ fun awakọ keke Maruwa lati gbe okunrin ati obinrin papọ nipinlẹ ọhun. Ajọ ọlọpaa Sharia ipinlẹ naa, Hisbah sọ pe, lati ọjọ keji oṣu, Kinni ọdun 2020, ẹnikẹni ti wọn ba gba mu pe o ru ofin naa yoo jẹ iyan rẹ niṣu. Adari ajọ naa, Sheik Harun Ibn-Sina fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC. O ni, ijiya fun ẹni to ba tapa si ofin naa ni pe wọn yoo gbẹsẹ le kẹkẹ rẹ fun oṣu mẹfa, tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun marun un naira ati bulala mẹwaa. Ibn-Sina ṣalaye pe "Ofin yii ti wa lati ọdun 2005, ṣugbọn a ṣẹṣẹ fẹ bẹrẹ si ni muu lo ni, ki a le fọ ipinlẹ wa mọ." O ni lati akoko yii di ipari ọdun, awakọ maruwa to ba gbe obinrin ati okunrin papọ yoo ni lati ja ero kan silẹ. Ṣugbọn lati ọjọ keji oṣu, Kinni ọdun 2020 ni ijiya ni pẹrẹu yoo bẹrẹ fun awọn to ba tapa sofin naa. Ibn-Sina ni awọn ẹṣọ ajọ ọhun ti gunlẹ si gbogbo ijọba ibilẹ mẹrinlelogoji to wa nipinlẹ Kano lati fẹsẹ ofin ọhun mulẹ. O ni tọkọtaya lee wọ keke kan naa papọ ti wọn ba lee bura pe awọn mejeji ti gbera wọn niyawo.
https://www.bbc.com/yoruba/media-50918082
3politics
Akọ̀rọ̀yìn tó gbé ìròyìn yìí ṣì mí gbọ́ ní, Aregbesola kó tíì sọ̀rọ̀ lórí gbèsè Osun- Agbẹnusọ
Agbẹnusọ fun gomina ana nipinlẹ Osun, Rauf Aregbesola ni iroyin to lọ kiri pe ọga oun ti sọrọ lori ọrọ to n fa ede aiyede lọwọ laarin Gomina to sẹsẹ kogba wọle, Gboyega Oyetola ati Gomina tuntun, eyiun, Ademola Adeleke lori gbese owo nipinlẹ naa kii ṣe ohun ti oun sọ ni pato. Sola Fasure, ninu atẹjade to fi lede lowurọ ọjọ Aiku, ni ko si nkan to jẹ mọ Minisita fun ọrọ abẹlẹ ti sọrọ lori ọrọ ati pe akọroyin to ba oun sọrọ si oun gbọ ni. O ni oniruuru iroyin lo ti tẹ oun lẹti, to si ya oun lẹnu nitori pupọ ninu awọn ọrọ ti akọroyin naa ni oun sọ ni ko ki n ṣe ọrọ ti to oun rara “Mo ti ka omiruuru iroyin ti wọn ni Ogbeni Rauf Aregbesola sọ lori itakun ọrọ to n lọ lọwọ lori bii ijọba ṣe yawo nilpinlẹ Osun “Eyi ni lati sọ pe Minisita ko buwọlu atẹjade kankan lori ọrọ naa. Bakan an, ọrọ ti akọroyin kan gbe jade ni ko ki n ṣe ọrọ mi rara. “Ogbeni lọwọ bayii gbajumọ isẹ rẹ gẹgẹ bii minisita, ti ko si fẹ ki ohun kohun tabuku si isẹ rẹ, ti ko si fẹ fi ẹnikẹni tabuku si orukọ rẹ. “Ti Minisita ba ti sọrọ, a yoo kan si gbogbo ile isẹ irotin gẹgẹ bii a ṣe ma ṣe.” Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Osun, Rauf Aregbesola ti dá sí gbogbo ìfańfà tó ń wáyé láàárín gómìnà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbésẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà Gboyega Oyetola àti gómìnà tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ sórí ipò, Ademola Adeleke. Láti ìgbà tí wọ́n ti búra wọlé fún Adeleke gẹ́gẹ́ bí gómìnà ni onírúurú awuyewuye ti ń wáyé láàárín Oyetola àti Adeleke lórí gbèsè tí ìpínlẹ̀ náà jẹ kalẹ̀. Adeleke ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbèsè ni Oyetola fi kalẹ̀ fún òun àmọ́ Oyetola ń tẹnumọ wí pé òun kò gba gbèsè kankan fún ọdún mẹ́rin tí òun lò nípò. Lẹ́nu lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí tún ni Adeleke tún fẹ̀sùn kàn Oyetola wí pé ó gba gbèsè bílíọ̀nù méjìdínlógún náírà lẹ́yìn tó fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Keje ọdún 2022. Ṣùgbọ́n nígbà tó ń fèsì, Oyetola ní Adeleke kàn fẹ́ mọ̀-ọ́n-mọ̀ ba òun lórúkọ jẹ́ ni nítorí òun kò yá kọ́bọ̀ lọ́wọ́ ilé ìfowópamọ́ kankan fun gbogbo ìgbà tí òun lò nípò àti pé gbogbo gbèsè tó wà lọ́rùn ìpínlẹ̀ Osun jẹ́ èyí tí òun jogún lọ́wọ́ Aregbesola. Ní báyìí, Rauf Aregbesola ti wá dá si ọ̀rọ̀ náà. Aregbesola ní olùṣírò àgbà fún ìpínlẹ̀ Osun ló ní gbogbo ìwé ẹ̀rí bí ìjọba kọ̀ọ̀kan ṣe gba owó lọ́wọ́ àti pé òun ló le sọ bí ọ̀rọ̀ gbèsè ìpínlẹ̀ náà ṣe jẹ́ gan. Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Aregbesola, Sola Fasure fi síta ní gbèsè méjì gbòógì tí òun gbà nígbà tí òun wà ní gómínà Osun ló ti jẹ́ sísan tán. Ó ní àwọn yòókù jẹ́ èyí tí àwọn gbà lọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ àti pé ọdún pípẹ́ ni àwọn máa fi san owó náà padà fún ìjọba àpapọ̀. Ó fi kun pé díẹ̀díẹ̀ ni ìjọba àpapọ̀ yóò máa yọ owó náà títí tí àwọn fi máa sán owó náà tán. Fasure ní olùṣírò owó àgbà ní ìpínlẹ̀ Osun ló ní ìmọ̀ nípa gbogbo owó tó wà lápò ìjọba, gbogbo gbèsè tí ìjọba jẹ, ìgbà tí wọ́n gba gbèsè àti ibi tí wọ́n san gbèsè náà dé. Ó ní nítorí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ mọ̀ bí ọ̀rọ̀ gbèsè ìpínlẹ̀ Osun ṣe jẹ́ kó kàn sí olùṣírò owó àgbà. Bákan náà lọ rọ àwọn ènìyàn láti má dà á ti Aregbesola sí gbogbo awuyewuye tó ń lọ ní Osun nítorí àárín Adeleke àti Oyetola ni ọ̀rọ̀ náà wà. Ó tẹ̀síwájú pé Oyetola ló dá gbogbo wàhálà tó ń wáyé sílẹ̀ nítorí pé kò gbé ìjọba kalẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Fasure ní tó bá jẹ́ wí pé Oyetola yan ìgbìmọ̀ tí yóò gbé ìjọba lé gómìnà tuntun lọ́wọ́, gbogbo àwọn nǹkan tó ń fa awuyewuye yìí ni wọ́n á ti yanjú tí yóò sì wà ní àkọ́ọ́lẹ̀. Ó fi kún pé tí ìjọba tuntun bá fi lè gbé ọ̀rọ̀ náà lọ síwájú EFCC Oyetola máa ní ìṣoro tó pọ̀. Ẹ ó rántí pé a ti ṣaájú mú ìròyìn wá pé Gómìnà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípò ní ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola ti tẹnumọ pé òun kò yá kọ́bọ̀ láti ṣe ìjọba nígbà tí òun wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà. Agbẹnusọ Oyetola, Ismail Omipidan sọ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta pé tí gómìnà tuntun tó wà lórí ipò bá ní ẹ̀rí tó dáwọn lójú pé Oyetola yá owó kankan kí wọ́n fi síta kí gbogbo ayé ri. Omipidan ní gbogbo ìjọba Rauf Aregbesola ló jẹ gbèsè tó wà lọ́rùn ìpínlẹ̀ Osun àti pé ìbanilórúkọ jẹ́ lásán ni Adeleke ń ṣe fún Oyetola pẹ̀lú gbogbo ìròyìn irọ́ tí wọ́n ń gbé síta nípa rẹ̀. Ó ní àìmọ̀kan gómìnà tuntun ló jẹ́ kó máa ní Oyetola gba gbèsè bílíọ̀nù méjìdínlógún náírà ní èyí tó jẹ́ wí pé kò rí bẹ́ẹ̀. Ó wá pe gómìnà Ademola Adeleke nínà láti fi ọdún àti ìgbà tí ìjọba ìpínlẹ̀ Osun gba àwọn gbèsè náà síta fún gbogbo ènìyàn láti rí. Omipidan tẹ̀síwájú pé ó dàbií wí pé àwọn tó kọ àkọ́lẹ̀ tí gómìnà Adeleke kò ṣe ìwádìí dáadáa ní àbí wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ kàn fẹ́ bá Oyetola ní orúkọ jẹ́. Ó fi kun pé nígbà tí ọ̀gá òun ń gbé ìjọba kalẹ̀, òun tó kọ ni pé ìjọba àpapọ̀ ń fún àwọn bílíọ̀nù mẹ́ta ni oṣooṣù láti ṣàtìlẹyìn fún àwọn ìpínlẹ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nítorí àdínkù tó bá àbá ìsúná. Ó ní láti inú oṣù Kejìlá ọdún 2021 ni èyí sì ti bẹ̀rẹ̀ fún oṣù mẹ́fà gbáko àmọ́ bó ṣe wá di pé lẹ́yìn tí àwọn parí eto ìdìbò ni àwọn gba owó náà ni kò yé òun. Omipidan tún tẹnumọ pé àwọn kò yá owó kankan ní báǹkì fún ọdún mẹ́rin tí àwọn lò nípò àti pé tó bá dá ìjọba tuntun lójú kó fi iye tí wọ́n bá nínú akoto ijoba Osun nígbà tí wọ́n gba ipò nínú oṣù kọkànlá síta fún gbogbo ayé. Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti sọ pe gbese biliọnu mejidinlogun naira ni gomina ana, Gboyega Oyetola ya lẹyin to padanu ibo gomina ninu oṣu Keje, ọdun 2022 yii. O fi kun pe nigba ti yoo fi di inu oṣu Kọkanla ọdun 2022, apapọ iye owo ti ipinlẹ naa jẹ ti le diẹ ni irinwo biliọnu naira. Adeleke lo fi ọrọ naa lede nibi ipade kan pẹlu awọn lọbalọba, eyii to waye niluu Osogbo. Gẹgẹ bii ohun to sọ, gbese ọna mẹjọ ọtọtọtọ ni ijọba rẹ jogun lọwọ ijọba Oyetola, yatọ si awọn gbese owo oṣu ati owo ifẹyinti. O ni akoko ti yoo gba ipinlẹ Osun lati san owo naa pada yoo to ọdun mejidinlọgbọn. Adeleke ni “Ẹyin eeyan mi nipinlẹ Osun, apapọ iye gbese to wa nilẹ bayii jẹ ọọdunrun ati bilọnu mọkanlelọgbọn naira.” “Ti a ba fi biliọnu mẹrindinlọgọrin naira tii se gbese owo oṣu ati owo ifẹyinti kun, apapọ gbese naa yoo jẹ irinwo biliọnu ati biliọnu meje naira, bẹẹ ni a ko mọ iye owo ti a jẹ awọn agbaṣẹse.” “Iye to ku si apo iṣuna ijọba bayii jẹ owo oṣu oṣiṣẹ fun oṣu Kọkanla ọdun yii nikan, lẹyin naa, korofo ni apo iṣuna ijọba wa.” Adeleke ni o jẹ ohun iyalẹnu fun oun pe ijọba ana nipinlẹ Osun ya owo ti iye rẹ le ni ọọdunrun bilọnu naira lai sí ohun kan pato ti ijọba ọhun fi owo naa ṣe. Adeleke fi kun o ṣe pataki ti gomina ana, Gboyega Oyetola wa ṣalaye awọn ohun to fi owo to ya lorukọ ipinlẹ Osun ṣe. O ni “Gomina Oyetola gbọdọ ṣalaye bo ṣe na ₦‎331b lorukọ ipinlẹ Osun ti a ko si fi oju ri nnkankan ti wọn fi owo naa ṣe.” “O tun gbọdọ ṣalaye nipa biliọnu mejidinlogun naira owo to ya lẹyin to lulẹ ninu eto idibo saa keji rẹ to waye ninu oṣu Keje.” “Gomina Oyetola gbọdọ ṣalaye eredi ti ijọba Osun ṣe jẹ gbese owo oṣu ti iye rẹ to ₦‎76b lẹyin ti ijọba apapọ ṣeto iranwọ ₦‎50b owo oṣu fun awọn ijọba ipinlẹ.” Adeleke pari ọrọ rẹ pe awọn ile ifowopamọ ti ọrọ naa kan gbọdọ ṣalaye eredi ti wọn fi ya ijọba Oyetola lowo nigba ti wọn mọ pe saa ijọba rẹ ti pari.
Akọ̀rọ̀yìn tó gbé ìròyìn yìí ṣì mí gbọ́ ní, Aregbesola kó tíì sọ̀rọ̀ lórí gbèsè Osun- Agbẹnusọ Agbẹnusọ fun gomina ana nipinlẹ Osun, Rauf Aregbesola ni iroyin to lọ kiri pe ọga oun ti sọrọ lori ọrọ to n fa ede aiyede lọwọ laarin Gomina to sẹsẹ kogba wọle, Gboyega Oyetola ati Gomina tuntun, eyiun, Ademola Adeleke lori gbese owo nipinlẹ naa kii ṣe ohun ti oun sọ ni pato. Sola Fasure, ninu atẹjade to fi lede lowurọ ọjọ Aiku, ni ko si nkan to jẹ mọ Minisita fun ọrọ abẹlẹ ti sọrọ lori ọrọ ati pe akọroyin to ba oun sọrọ si oun gbọ ni. O ni oniruuru iroyin lo ti tẹ oun lẹti, to si ya oun lẹnu nitori pupọ ninu awọn ọrọ ti akọroyin naa ni oun sọ ni ko ki n ṣe ọrọ ti to oun rara “Mo ti ka omiruuru iroyin ti wọn ni Ogbeni Rauf Aregbesola sọ lori itakun ọrọ to n lọ lọwọ lori bii ijọba ṣe yawo nilpinlẹ Osun “Eyi ni lati sọ pe Minisita ko buwọlu atẹjade kankan lori ọrọ naa. Bakan an, ọrọ ti akọroyin kan gbe jade ni ko ki n ṣe ọrọ mi rara. “Ogbeni lọwọ bayii gbajumọ isẹ rẹ gẹgẹ bii minisita, ti ko si fẹ ki ohun kohun tabuku si isẹ rẹ, ti ko si fẹ fi ẹnikẹni tabuku si orukọ rẹ. “Ti Minisita ba ti sọrọ, a yoo kan si gbogbo ile isẹ irotin gẹgẹ bii a ṣe ma ṣe.” Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Osun, Rauf Aregbesola ti dá sí gbogbo ìfańfà tó ń wáyé láàárín gómìnà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbésẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà Gboyega Oyetola àti gómìnà tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ sórí ipò, Ademola Adeleke. Láti ìgbà tí wọ́n ti búra wọlé fún Adeleke gẹ́gẹ́ bí gómìnà ni onírúurú awuyewuye ti ń wáyé láàárín Oyetola àti Adeleke lórí gbèsè tí ìpínlẹ̀ náà jẹ kalẹ̀. Adeleke ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbèsè ni Oyetola fi kalẹ̀ fún òun àmọ́ Oyetola ń tẹnumọ wí pé òun kò gba gbèsè kankan fún ọdún mẹ́rin tí òun lò nípò. Lẹ́nu lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí tún ni Adeleke tún fẹ̀sùn kàn Oyetola wí pé ó gba gbèsè bílíọ̀nù méjìdínlógún náírà lẹ́yìn tó fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Keje ọdún 2022. Ṣùgbọ́n nígbà tó ń fèsì, Oyetola ní Adeleke kàn fẹ́ mọ̀-ọ́n-mọ̀ ba òun lórúkọ jẹ́ ni nítorí òun kò yá kọ́bọ̀ lọ́wọ́ ilé ìfowópamọ́ kankan fun gbogbo ìgbà tí òun lò nípò àti pé gbogbo gbèsè tó wà lọ́rùn ìpínlẹ̀ Osun jẹ́ èyí tí òun jogún lọ́wọ́ Aregbesola. Ní báyìí, Rauf Aregbesola ti wá dá si ọ̀rọ̀ náà. Aregbesola ní olùṣírò àgbà fún ìpínlẹ̀ Osun ló ní gbogbo ìwé ẹ̀rí bí ìjọba kọ̀ọ̀kan ṣe gba owó lọ́wọ́ àti pé òun ló le sọ bí ọ̀rọ̀ gbèsè ìpínlẹ̀ náà ṣe jẹ́ gan. Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Aregbesola, Sola Fasure fi síta ní gbèsè méjì gbòógì tí òun gbà nígbà tí òun wà ní gómínà Osun ló ti jẹ́ sísan tán. Ó ní àwọn yòókù jẹ́ èyí tí àwọn gbà lọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ àti pé ọdún pípẹ́ ni àwọn máa fi san owó náà padà fún ìjọba àpapọ̀. Ó fi kun pé díẹ̀díẹ̀ ni ìjọba àpapọ̀ yóò máa yọ owó náà títí tí àwọn fi máa sán owó náà tán. Fasure ní olùṣírò owó àgbà ní ìpínlẹ̀ Osun ló ní ìmọ̀ nípa gbogbo owó tó wà lápò ìjọba, gbogbo gbèsè tí ìjọba jẹ, ìgbà tí wọ́n gba gbèsè àti ibi tí wọ́n san gbèsè náà dé. Ó ní nítorí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ mọ̀ bí ọ̀rọ̀ gbèsè ìpínlẹ̀ Osun ṣe jẹ́ kó kàn sí olùṣírò owó àgbà. Bákan náà lọ rọ àwọn ènìyàn láti má dà á ti Aregbesola sí gbogbo awuyewuye tó ń lọ ní Osun nítorí àárín Adeleke àti Oyetola ni ọ̀rọ̀ náà wà. Ó tẹ̀síwájú pé Oyetola ló dá gbogbo wàhálà tó ń wáyé sílẹ̀ nítorí pé kò gbé ìjọba kalẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Fasure ní tó bá jẹ́ wí pé Oyetola yan ìgbìmọ̀ tí yóò gbé ìjọba lé gómìnà tuntun lọ́wọ́, gbogbo àwọn nǹkan tó ń fa awuyewuye yìí ni wọ́n á ti yanjú tí yóò sì wà ní àkọ́ọ́lẹ̀. Ó fi kún pé tí ìjọba tuntun bá fi lè gbé ọ̀rọ̀ náà lọ síwájú EFCC Oyetola máa ní ìṣoro tó pọ̀. Ẹ ó rántí pé a ti ṣaájú mú ìròyìn wá pé Gómìnà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípò ní ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola ti tẹnumọ pé òun kò yá kọ́bọ̀ láti ṣe ìjọba nígbà tí òun wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà. Agbẹnusọ Oyetola, Ismail Omipidan sọ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta pé tí gómìnà tuntun tó wà lórí ipò bá ní ẹ̀rí tó dáwọn lójú pé Oyetola yá owó kankan kí wọ́n fi síta kí gbogbo ayé ri. Omipidan ní gbogbo ìjọba Rauf Aregbesola ló jẹ gbèsè tó wà lọ́rùn ìpínlẹ̀ Osun àti pé ìbanilórúkọ jẹ́ lásán ni Adeleke ń ṣe fún Oyetola pẹ̀lú gbogbo ìròyìn irọ́ tí wọ́n ń gbé síta nípa rẹ̀. Ó ní àìmọ̀kan gómìnà tuntun ló jẹ́ kó máa ní Oyetola gba gbèsè bílíọ̀nù méjìdínlógún náírà ní èyí tó jẹ́ wí pé kò rí bẹ́ẹ̀. Ó wá pe gómìnà Ademola Adeleke nínà láti fi ọdún àti ìgbà tí ìjọba ìpínlẹ̀ Osun gba àwọn gbèsè náà síta fún gbogbo ènìyàn láti rí. Omipidan tẹ̀síwájú pé ó dàbií wí pé àwọn tó kọ àkọ́lẹ̀ tí gómìnà Adeleke kò ṣe ìwádìí dáadáa ní àbí wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ kàn fẹ́ bá Oyetola ní orúkọ jẹ́. Ó fi kun pé nígbà tí ọ̀gá òun ń gbé ìjọba kalẹ̀, òun tó kọ ni pé ìjọba àpapọ̀ ń fún àwọn bílíọ̀nù mẹ́ta ni oṣooṣù láti ṣàtìlẹyìn fún àwọn ìpínlẹ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nítorí àdínkù tó bá àbá ìsúná. Ó ní láti inú oṣù Kejìlá ọdún 2021 ni èyí sì ti bẹ̀rẹ̀ fún oṣù mẹ́fà gbáko àmọ́ bó ṣe wá di pé lẹ́yìn tí àwọn parí eto ìdìbò ni àwọn gba owó náà ni kò yé òun. Omipidan tún tẹnumọ pé àwọn kò yá owó kankan ní báǹkì fún ọdún mẹ́rin tí àwọn lò nípò àti pé tó bá dá ìjọba tuntun lójú kó fi iye tí wọ́n bá nínú akoto ijoba Osun nígbà tí wọ́n gba ipò nínú oṣù kọkànlá síta fún gbogbo ayé. Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti sọ pe gbese biliọnu mejidinlogun naira ni gomina ana, Gboyega Oyetola ya lẹyin to padanu ibo gomina ninu oṣu Keje, ọdun 2022 yii. O fi kun pe nigba ti yoo fi di inu oṣu Kọkanla ọdun 2022, apapọ iye owo ti ipinlẹ naa jẹ ti le diẹ ni irinwo biliọnu naira. Adeleke lo fi ọrọ naa lede nibi ipade kan pẹlu awọn lọbalọba, eyii to waye niluu Osogbo. Gẹgẹ bii ohun to sọ, gbese ọna mẹjọ ọtọtọtọ ni ijọba rẹ jogun lọwọ ijọba Oyetola, yatọ si awọn gbese owo oṣu ati owo ifẹyinti. O ni akoko ti yoo gba ipinlẹ Osun lati san owo naa pada yoo to ọdun mejidinlọgbọn. Adeleke ni “Ẹyin eeyan mi nipinlẹ Osun, apapọ iye gbese to wa nilẹ bayii jẹ ọọdunrun ati bilọnu mọkanlelọgbọn naira.” “Ti a ba fi biliọnu mẹrindinlọgọrin naira tii se gbese owo oṣu ati owo ifẹyinti kun, apapọ gbese naa yoo jẹ irinwo biliọnu ati biliọnu meje naira, bẹẹ ni a ko mọ iye owo ti a jẹ awọn agbaṣẹse.” “Iye to ku si apo iṣuna ijọba bayii jẹ owo oṣu oṣiṣẹ fun oṣu Kọkanla ọdun yii nikan, lẹyin naa, korofo ni apo iṣuna ijọba wa.” Adeleke ni o jẹ ohun iyalẹnu fun oun pe ijọba ana nipinlẹ Osun ya owo ti iye rẹ le ni ọọdunrun bilọnu naira lai sí ohun kan pato ti ijọba ọhun fi owo naa ṣe. Adeleke fi kun o ṣe pataki ti gomina ana, Gboyega Oyetola wa ṣalaye awọn ohun to fi owo to ya lorukọ ipinlẹ Osun ṣe. O ni “Gomina Oyetola gbọdọ ṣalaye bo ṣe na ₦‎331b lorukọ ipinlẹ Osun ti a ko si fi oju ri nnkankan ti wọn fi owo naa ṣe.” “O tun gbọdọ ṣalaye nipa biliọnu mejidinlogun naira owo to ya lẹyin to lulẹ ninu eto idibo saa keji rẹ to waye ninu oṣu Keje.” “Gomina Oyetola gbọdọ ṣalaye eredi ti ijọba Osun ṣe jẹ gbese owo oṣu ti iye rẹ to ₦‎76b lẹyin ti ijọba apapọ ṣeto iranwọ ₦‎50b owo oṣu fun awọn ijọba ipinlẹ.” Adeleke pari ọrọ rẹ pe awọn ile ifowopamọ ti ọrọ naa kan gbọdọ ṣalaye eredi ti wọn fi ya ijọba Oyetola lowo nigba ti wọn mọ pe saa ijọba rẹ ti pari.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c3g1080przxo
3politics
Yoruba Nation: Ìjọba Nàìjíríà ló ń dún mọ̀huru mọ́ Benin Republic lati dé Sunday Igboho mọ́ àhámọ́ - Gani Adams
Aarẹ Ọna kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti fi aidunu rẹ han lori bi Oloye Sunday Adeyẹmọ ṣi ṣe wa ni ahamo. O ni ko tẹ oun lọrun bi ẹni ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ṣe n pẹ ni atimọle lorilẹede Benin Republi. Koda, Iba Adams ṣalaye pe o da oun loju pe ijọba apapọ Naijiria lo wa nidi bi wọn ṣe ti lẹkun ahamọ mọ Sunday Igboho ti wọn si ju kọkọrọ rẹ nu. Ninu ọrọ kan to sọ nibi ipade akọroyin kan to fi n sami ayajọ ọdun kẹrin rẹ nipo gẹgẹ bii aarẹ ọna kakanfo ẹlẹkarundinlogun ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ni ko si ijọba to nifẹ awọn eeyan rẹ ti yoo gba ki iru iṣẹlẹ bẹẹ waye. "Ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba ni Sunday Igboho pe, ko jagun, bẹẹ ni ko si gbe ibọn, ijijangbara alaafia lo n ba kiri. Ijọba ran awọn agbofinro lọ baa nile, wọn pa eeyan meji nibẹ ti wọn ko si tii fi oku wọn silẹ titi di bi a ṣe n sọrọ yii." Gani Adams ni iwadii oun ti fihan pe ijọba Naijiria n du mọhuru mọ ijọba Benin Republic ni wọn fi n tilẹkun ọgba ẹwọn mọọ lai pe e lẹjọnile ẹjọ. O wa rọ Aarẹ Buhari lati tu okun lọrun Igboho ati Nnamdi Kanu nitori ominira ati idagbasoke agbegbe wọn ni wọn n ja fun.
Yoruba Nation: Ìjọba Nàìjíríà ló ń dún mọ̀huru mọ́ Benin Republic lati dé Sunday Igboho mọ́ àhámọ́ - Gani Adams Aarẹ Ọna kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti fi aidunu rẹ han lori bi Oloye Sunday Adeyẹmọ ṣi ṣe wa ni ahamo. O ni ko tẹ oun lọrun bi ẹni ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ṣe n pẹ ni atimọle lorilẹede Benin Republi. Koda, Iba Adams ṣalaye pe o da oun loju pe ijọba apapọ Naijiria lo wa nidi bi wọn ṣe ti lẹkun ahamọ mọ Sunday Igboho ti wọn si ju kọkọrọ rẹ nu. Ninu ọrọ kan to sọ nibi ipade akọroyin kan to fi n sami ayajọ ọdun kẹrin rẹ nipo gẹgẹ bii aarẹ ọna kakanfo ẹlẹkarundinlogun ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ni ko si ijọba to nifẹ awọn eeyan rẹ ti yoo gba ki iru iṣẹlẹ bẹẹ waye. "Ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba ni Sunday Igboho pe, ko jagun, bẹẹ ni ko si gbe ibọn, ijijangbara alaafia lo n ba kiri. Ijọba ran awọn agbofinro lọ baa nile, wọn pa eeyan meji nibẹ ti wọn ko si tii fi oku wọn silẹ titi di bi a ṣe n sọrọ yii." Gani Adams ni iwadii oun ti fihan pe ijọba Naijiria n du mọhuru mọ ijọba Benin Republic ni wọn fi n tilẹkun ọgba ẹwọn mọọ lai pe e lẹjọnile ẹjọ. O wa rọ Aarẹ Buhari lati tu okun lọrun Igboho ati Nnamdi Kanu nitori ominira ati idagbasoke agbegbe wọn ni wọn n ja fun.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60014172
4religion
Eid Mubarak: Àràmọ̀ǹdà àwòràn ìkíni ọdún Eid il Fitr òṣèré tíátà Yorùbá àti gbajúmọ̀ míràn rèé
Jakejado Naijriia lawọn musulumi ti n ṣe ajọdun Eid il Fitr. Ko yọ awọn elere tiata ati gbajumọ mii silẹ.
Eid Mubarak: Àràmọ̀ǹdà àwòràn ìkíni ọdún Eid il Fitr òṣèré tíátà Yorùbá àti gbajúmọ̀ míràn rèé Jakejado Naijriia lawọn musulumi ti n ṣe ajọdun Eid il Fitr. Ko yọ awọn elere tiata ati gbajumọ mii silẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61299884
2health
Beer Belly: Wo ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa ikun rẹ tó ń to tobi
Njẹ o jẹ eeyan to maa n mu ọti bia (Beer), abi o mọ ọti bia funra rẹ? To ba ri bẹẹ, iroyin yii kan ọ. Aye ijọhun ni wọn maa n ri ọjọ ori gẹgẹ bii ami fun ọrọ ti ẹda ni, ti ọpọ si maa n fi ikun titobi yangan ni awujọ. Sugbọn bayii, inu fẹ́lẹ́ ti ti ebi kọ ni awọn eeyan n fẹ ninu eyi ti ọpọ ọkunrin si maa n gba ibudo ere idaraya lọ lati mọ bi wọn se ri, ki wọn si din ọra ikun wọn ku. Awọn ọpọ ọdun ta maa n ri awọn baba ati arakunrin wa ti wọn maa n gbe bia kiri ti waye sẹyin. Bia ta n gbe kiri yii, ni awọn oloyinbo ni pe o ni ohun ti a n pe ni 'Calorie' eyi to n mu ki eeyan sanra, ti ohun mimu naa si wuwo ninu ara. Nitoripe awọn ọkunrin kan maa n mu ju igo ọti kan lọ nibudo imuti kan, ti wọn ko si ni lero lati se ere idaraya lẹyin mimu ọti yii naa maa n fi kun 'Calorie'ara ni. Sugbọn laarin awọn obinrin, wahala yii maa n tọ ara wọn ja ni, ti yoo si wọ wọn de ori ẹsẹ wọn. A si lee pe akoko ti bia lee ba ara mu ni igba ewe si ọdun marundinlogoji, lati akoko yii lọ, isọwọ sisẹ eroja to n mu ki ounjẹ tete da ninu ara, ko ni sisẹ bo se yẹ mọ. Nigba ti ounjẹ ko ba si da bo se ni kiakia gẹgẹ bo se maa n se tẹlẹ lasiko ti eeyan wa ni ọdọ, itumọ eyi ni pe onitọhun ko sisẹ asekara to yẹ, ti yoo si maa ba ikun rẹ ja. Ọti bia nikan kọ lo n sokunfa bi ikun se n tobi, amọ eroja ọra kan ti wọn pe ni 'Visceral' lo n sokunfa ikun to tobi. Bakan naa, awọn eeyan to ni aisan atọgbẹ tabi itọ suga, aisan ọkan atawọn oniruuru aisan miran to maa n sediwọ fun eroja insulin lati sisẹ ninu ara, naa maa n fa ki ikun tobi. Awọn dokita ati onimọ nipa ounjẹ asaraloore ni ọra ikun naa lee maa pọ si to ba se ayipada awọn eroja ounjẹ to n jẹ, paapa apọju awọn ounjẹ to ni eroja suga atawọn ounjẹ afun ara lagbara. Kini ọna abayọ? Ọna abayọ to wa fun ọ, to ba ni ikun to tobi ni pe ko se adinku suga ati ounjẹ afara lagbara to n jẹ, taa mọ si Carbonhydrate, jẹ ounjẹ niwọn tun wọnsi, ko si maa sinmi.
Beer Belly: Wo ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa ikun rẹ tó ń to tobi Njẹ o jẹ eeyan to maa n mu ọti bia (Beer), abi o mọ ọti bia funra rẹ? To ba ri bẹẹ, iroyin yii kan ọ. Aye ijọhun ni wọn maa n ri ọjọ ori gẹgẹ bii ami fun ọrọ ti ẹda ni, ti ọpọ si maa n fi ikun titobi yangan ni awujọ. Sugbọn bayii, inu fẹ́lẹ́ ti ti ebi kọ ni awọn eeyan n fẹ ninu eyi ti ọpọ ọkunrin si maa n gba ibudo ere idaraya lọ lati mọ bi wọn se ri, ki wọn si din ọra ikun wọn ku. Awọn ọpọ ọdun ta maa n ri awọn baba ati arakunrin wa ti wọn maa n gbe bia kiri ti waye sẹyin. Bia ta n gbe kiri yii, ni awọn oloyinbo ni pe o ni ohun ti a n pe ni 'Calorie' eyi to n mu ki eeyan sanra, ti ohun mimu naa si wuwo ninu ara. Nitoripe awọn ọkunrin kan maa n mu ju igo ọti kan lọ nibudo imuti kan, ti wọn ko si ni lero lati se ere idaraya lẹyin mimu ọti yii naa maa n fi kun 'Calorie'ara ni. Sugbọn laarin awọn obinrin, wahala yii maa n tọ ara wọn ja ni, ti yoo si wọ wọn de ori ẹsẹ wọn. A si lee pe akoko ti bia lee ba ara mu ni igba ewe si ọdun marundinlogoji, lati akoko yii lọ, isọwọ sisẹ eroja to n mu ki ounjẹ tete da ninu ara, ko ni sisẹ bo se yẹ mọ. Nigba ti ounjẹ ko ba si da bo se ni kiakia gẹgẹ bo se maa n se tẹlẹ lasiko ti eeyan wa ni ọdọ, itumọ eyi ni pe onitọhun ko sisẹ asekara to yẹ, ti yoo si maa ba ikun rẹ ja. Ọti bia nikan kọ lo n sokunfa bi ikun se n tobi, amọ eroja ọra kan ti wọn pe ni 'Visceral' lo n sokunfa ikun to tobi. Bakan naa, awọn eeyan to ni aisan atọgbẹ tabi itọ suga, aisan ọkan atawọn oniruuru aisan miran to maa n sediwọ fun eroja insulin lati sisẹ ninu ara, naa maa n fa ki ikun tobi. Awọn dokita ati onimọ nipa ounjẹ asaraloore ni ọra ikun naa lee maa pọ si to ba se ayipada awọn eroja ounjẹ to n jẹ, paapa apọju awọn ounjẹ to ni eroja suga atawọn ounjẹ afun ara lagbara. Kini ọna abayọ? Ọna abayọ to wa fun ọ, to ba ni ikun to tobi ni pe ko se adinku suga ati ounjẹ afara lagbara to n jẹ, taa mọ si Carbonhydrate, jẹ ounjẹ niwọn tun wọnsi, ko si maa sinmi.
https://www.bbc.com/yoruba/agbaye-51499516
3politics
Gómìnà Adeleke gbé ìgbìmọ̀ kalẹ̀ fún pínpín ìrẹsì ọdún l'Osun
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke ti gbe igbimọ kan kalẹ fun pinpin irẹsi ọdun fun awọn eeyan ipinlẹ naa. Gẹgẹbi atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọṣun, Rasheed Ọlawale gbe sita, eto pinpin irẹsi naa ko niiṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu tabi ilu tabi ohunkohun. Ijọba ipinlẹ Ọṣun ni ogoji apo irẹsi  ti iye ọkọọkan rẹ jẹ naira mejilelọgbọn (N32, 000) ni wọn yoo pin fun wọọdu kọọkan. Pẹlu agbekalẹ eto idibo ipinlẹ Ọṣun to kọja, wọọdu ọdunrunlemejilelọgbọn lo wa ni ipinlẹ Ọṣun. Eyi tumọ si pe ẹgbẹrun mẹtala ati ọrinlelugba (13,280) apo irẹsi ni ijọba ipinlẹ Ọṣun fẹ pin. Atẹjade naa ko sọ igba ti pinpin irẹsi naa yoo bẹrẹ ni ipinlẹ naa. Awọn meje ti yoo wa ninu igbimọ naa ni:
Gómìnà Adeleke gbé ìgbìmọ̀ kalẹ̀ fún pínpín ìrẹsì ọdún l'Osun Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke ti gbe igbimọ kan kalẹ fun pinpin irẹsi ọdun fun awọn eeyan ipinlẹ naa. Gẹgẹbi atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọṣun, Rasheed Ọlawale gbe sita, eto pinpin irẹsi naa ko niiṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu tabi ilu tabi ohunkohun. Ijọba ipinlẹ Ọṣun ni ogoji apo irẹsi  ti iye ọkọọkan rẹ jẹ naira mejilelọgbọn (N32, 000) ni wọn yoo pin fun wọọdu kọọkan. Pẹlu agbekalẹ eto idibo ipinlẹ Ọṣun to kọja, wọọdu ọdunrunlemejilelọgbọn lo wa ni ipinlẹ Ọṣun. Eyi tumọ si pe ẹgbẹrun mẹtala ati ọrinlelugba (13,280) apo irẹsi ni ijọba ipinlẹ Ọṣun fẹ pin. Atẹjade naa ko sọ igba ti pinpin irẹsi naa yoo bẹrẹ ni ipinlẹ naa. Awọn meje ti yoo wa ninu igbimọ naa ni:
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c7272vl928vo
3politics
Kogi: Ilé aṣòfin ti bẹ́rẹ́ ìgbésẹ̀ àti rọ igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi lóyè
Afaimọ ki ipinlẹ Kogi maa ni igbakeji gomina miran laipẹ. Ti iku kọ, bẹẹ ni kii ṣe ti arun, ṣugbọn o ṣee ṣe ki iji aawọ to n waye laarin igbakeji gomina ipinlẹ Kogi, Simon Achuba ati Ọga rẹ, iyẹn gomina Bello o gbe igbakeji gomina naa lọ. Gẹgẹ bii ara apẹrẹ iji naa ni bi ile aṣofin ipinlẹ kogi ṣe bẹrẹ igbesẹ ati rọọ loye ni ọjọ iṣẹgun. Ile aṣofin ipinlẹ naa ti ke si adajọ agba ipinlẹ naa, Onidajọ Nasir Ajanah lati gbe igbimọ ẹlẹni meje kan kalẹ lati se iwadii awọn ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan igbakeji gomina naa. Kike si adajọ agba lati gbe igbimọ oluwadi kalẹ ni igbesẹ keji ti ofin orilẹede Naijiria la kalẹ fun yiyọ awọn to ba di ipo mu bii aarẹ, igbakeji aarẹ, gomina ati igbakeji gomina ipinlẹ lorilẹede Naijiria. Olori ọmọẹgbẹ oṣelu to pọ julọ nile aṣofin ipinlẹ Kogi, Abdullahi Bello-Balogun lo lewaju aba kan ti wọn gbe ka iwaju ile naa lori ẹsun pe igbakeji gomina ọhun gbiyanju ati da yẹyẹ gomina Yahaya Bello ati ijsba ipinlẹ naa sita gbangba ati pe gbangba bayii lo ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ alatako lasiko idibo aarẹ to kọja. Mẹtadinlogun ninu aṣofin mọkandinlogun to wa ni ile naa ni wọn fi ọwọ si igbesẹ naa; ti wọn si fun adajọ agba ni gbedeke ọjọ meje lati gbe igbesẹ agbekalẹ igbimọ naa. Laipẹ yii ni Igbakeji gomina ipinlẹ Kogi, Simon Achuba pariwo fun aye gbọ lasiko to ba awọn oniroyin sọrọ pe aarin oun ati ọga oun ko gun eyi to jẹ koko ninu gbun-gbun-gbun to ti n waye laarin awọn mejeeji lati igba diẹ sẹyin. Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, agbẹnusọ fun Olori ié aṣofin ipinlẹ Kogi, Ọgbẹni Fẹmi Olugbemi ni igbesẹ ti Achuba gbe lati lọ sọ ọrọ ile si ita gbangba dipo ko wa siwaju ile naa lati fi ẹjọ ọga rẹ sun, iyẹn bi ọga rẹ ba ṣẹ ẹ nitotọ lo jẹ ki wọn gbe igbesẹ naa. Amọṣa, gomina ipinlẹ Kogi ni oun ko mọ nipa ohun ti oju igbakeji oun n ri lọwọlọwọ. Agbẹnusọ fun un, Onogu Muhammed ni Gomina Bello ko mọ ni pa oun to waye nile aṣofin ipinlẹ naa nitori awọn n bọwọ fun eto konko jabele kaluku lo mi ṣe ti ẹ laarin awọn ẹka ijọba gbogbo nibẹ.
Kogi: Ilé aṣòfin ti bẹ́rẹ́ ìgbésẹ̀ àti rọ igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi lóyè Afaimọ ki ipinlẹ Kogi maa ni igbakeji gomina miran laipẹ. Ti iku kọ, bẹẹ ni kii ṣe ti arun, ṣugbọn o ṣee ṣe ki iji aawọ to n waye laarin igbakeji gomina ipinlẹ Kogi, Simon Achuba ati Ọga rẹ, iyẹn gomina Bello o gbe igbakeji gomina naa lọ. Gẹgẹ bii ara apẹrẹ iji naa ni bi ile aṣofin ipinlẹ kogi ṣe bẹrẹ igbesẹ ati rọọ loye ni ọjọ iṣẹgun. Ile aṣofin ipinlẹ naa ti ke si adajọ agba ipinlẹ naa, Onidajọ Nasir Ajanah lati gbe igbimọ ẹlẹni meje kan kalẹ lati se iwadii awọn ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan igbakeji gomina naa. Kike si adajọ agba lati gbe igbimọ oluwadi kalẹ ni igbesẹ keji ti ofin orilẹede Naijiria la kalẹ fun yiyọ awọn to ba di ipo mu bii aarẹ, igbakeji aarẹ, gomina ati igbakeji gomina ipinlẹ lorilẹede Naijiria. Olori ọmọẹgbẹ oṣelu to pọ julọ nile aṣofin ipinlẹ Kogi, Abdullahi Bello-Balogun lo lewaju aba kan ti wọn gbe ka iwaju ile naa lori ẹsun pe igbakeji gomina ọhun gbiyanju ati da yẹyẹ gomina Yahaya Bello ati ijsba ipinlẹ naa sita gbangba ati pe gbangba bayii lo ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ alatako lasiko idibo aarẹ to kọja. Mẹtadinlogun ninu aṣofin mọkandinlogun to wa ni ile naa ni wọn fi ọwọ si igbesẹ naa; ti wọn si fun adajọ agba ni gbedeke ọjọ meje lati gbe igbesẹ agbekalẹ igbimọ naa. Laipẹ yii ni Igbakeji gomina ipinlẹ Kogi, Simon Achuba pariwo fun aye gbọ lasiko to ba awọn oniroyin sọrọ pe aarin oun ati ọga oun ko gun eyi to jẹ koko ninu gbun-gbun-gbun to ti n waye laarin awọn mejeeji lati igba diẹ sẹyin. Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, agbẹnusọ fun Olori ié aṣofin ipinlẹ Kogi, Ọgbẹni Fẹmi Olugbemi ni igbesẹ ti Achuba gbe lati lọ sọ ọrọ ile si ita gbangba dipo ko wa siwaju ile naa lati fi ẹjọ ọga rẹ sun, iyẹn bi ọga rẹ ba ṣẹ ẹ nitotọ lo jẹ ki wọn gbe igbesẹ naa. Amọṣa, gomina ipinlẹ Kogi ni oun ko mọ nipa ohun ti oju igbakeji oun n ri lọwọlọwọ. Agbẹnusọ fun un, Onogu Muhammed ni Gomina Bello ko mọ ni pa oun to waye nile aṣofin ipinlẹ naa nitori awọn n bọwọ fun eto konko jabele kaluku lo mi ṣe ti ẹ laarin awọn ẹka ijọba gbogbo nibẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/49412409
2health
Muhammadu Buhari: Falana ní ilé ìwòsàn ti di mọ́ṣúárì ní Nàìjíríà nígbà tí Buhari ń gbàtọ́jú nílẹ̀ òkèrè
Ẹyin ọmọ Naijiria, ẹtọ yin lati beere fun eto ilera to peye lọwọ ijọba aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari. Agbẹjọro ati ajafẹtọ, Femi Falana lo sọrọ yii idanilẹkọ ọdọọdun fun iranti Dokita Beko Ransome-Kuti ẹlẹẹkẹrinla rẹ. Agbẹjọro Falana sọ pe ijọba ologun Buhari lo ju Dokita Beko si ọgba ẹwọn Kirikiri fun oṣu mẹfa lọdun 1984 nitori o jijagbara lati beere fun eto ilera to peye lọwọ ijọba. Falana sọ pe ohun to kudiẹ kaato ni pe aarẹ Buhari n rinrin ajo lọ si oke okun fun itọju ara rẹ, nigba ti awọn ọmọ Naijiria n lọ si awọn ile iwosan to ti di mọṣuari bayii. O ni Buhari fun ra rẹ lo nigba to gori aleefa gẹgẹ bi ọgagun olori orilẹede Naijiria lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 1983 pe awọn ile iwosan ni Naijiria ti di ibi ti awọn eeyan ti n ri awọn dokita lasan an. Falana ṣalaye pe Buhari kan naa to sọrọ lọdun 1984 pe awọn ile iwosan to wa ni Naijiria ko ju ibi tawọn eeyan kan ti n ri awọn dokita lasan lọ, oun naa si ni aarẹ Naijiria lonii ti awọn iwosan ti di mọṣuari. Gbajugbaja agbẹjọro ni Buhari ko lọ si awọn ile iwosan yii, ilu oyinbo lo n lọ fun itọju ara rẹ, owo ilu lo si n na. ''Ẹjọ ti mo pe ijọba wa ni ileẹjọ kotẹmilọrun bayii ninu eyi ti mo ti sọ pe ki ijọba ṣe eto iwosan to peye fun gbogbo eeyan nitori ori ko ju ori,'' Falana lo sọ bẹẹ. ''Ti ẹyin ba n gba ilu oyinbo lọ fun itọju, ẹ gbọdọ ba wa ṣe awọn ile iwosan ti awa naa n lo nile ko dara, ka wa naa le lanfaani si eto ilera to peye,'' Falana lo woye bẹẹ. Falana tun fi kun ọrọ rẹ pe Buhari naa ni o fa iya to n jẹ ọpọ ara ilu Eko bayii lẹyin ti ijọba f'ofin de ọkada ati kẹkẹ Maruwa nitori o wọgile aba lati ṣe eto igbokegbodo ọkọ ti igbalode oni igba nmiliọnu dọla($200m) eyi ti Gomina Lateef Jakande ṣe agbekalẹ rẹ lasiko to wa lori alefa.
Muhammadu Buhari: Falana ní ilé ìwòsàn ti di mọ́ṣúárì ní Nàìjíríà nígbà tí Buhari ń gbàtọ́jú nílẹ̀ òkèrè Ẹyin ọmọ Naijiria, ẹtọ yin lati beere fun eto ilera to peye lọwọ ijọba aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari. Agbẹjọro ati ajafẹtọ, Femi Falana lo sọrọ yii idanilẹkọ ọdọọdun fun iranti Dokita Beko Ransome-Kuti ẹlẹẹkẹrinla rẹ. Agbẹjọro Falana sọ pe ijọba ologun Buhari lo ju Dokita Beko si ọgba ẹwọn Kirikiri fun oṣu mẹfa lọdun 1984 nitori o jijagbara lati beere fun eto ilera to peye lọwọ ijọba. Falana sọ pe ohun to kudiẹ kaato ni pe aarẹ Buhari n rinrin ajo lọ si oke okun fun itọju ara rẹ, nigba ti awọn ọmọ Naijiria n lọ si awọn ile iwosan to ti di mọṣuari bayii. O ni Buhari fun ra rẹ lo nigba to gori aleefa gẹgẹ bi ọgagun olori orilẹede Naijiria lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 1983 pe awọn ile iwosan ni Naijiria ti di ibi ti awọn eeyan ti n ri awọn dokita lasan an. Falana ṣalaye pe Buhari kan naa to sọrọ lọdun 1984 pe awọn ile iwosan to wa ni Naijiria ko ju ibi tawọn eeyan kan ti n ri awọn dokita lasan lọ, oun naa si ni aarẹ Naijiria lonii ti awọn iwosan ti di mọṣuari. Gbajugbaja agbẹjọro ni Buhari ko lọ si awọn ile iwosan yii, ilu oyinbo lo n lọ fun itọju ara rẹ, owo ilu lo si n na. ''Ẹjọ ti mo pe ijọba wa ni ileẹjọ kotẹmilọrun bayii ninu eyi ti mo ti sọ pe ki ijọba ṣe eto iwosan to peye fun gbogbo eeyan nitori ori ko ju ori,'' Falana lo sọ bẹẹ. ''Ti ẹyin ba n gba ilu oyinbo lọ fun itọju, ẹ gbọdọ ba wa ṣe awọn ile iwosan ti awa naa n lo nile ko dara, ka wa naa le lanfaani si eto ilera to peye,'' Falana lo woye bẹẹ. Falana tun fi kun ọrọ rẹ pe Buhari naa ni o fa iya to n jẹ ọpọ ara ilu Eko bayii lẹyin ti ijọba f'ofin de ọkada ati kẹkẹ Maruwa nitori o wọgile aba lati ṣe eto igbokegbodo ọkọ ti igbalode oni igba nmiliọnu dọla($200m) eyi ti Gomina Lateef Jakande ṣe agbekalẹ rẹ lasiko to wa lori alefa.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51440209
2health
Body odour solution: Wo ǹkan tó ń fa 'body odour' àti bí o ṣè lè ṣẹ́gun rẹ̀
Àwọn onimọ sọ pe ọpọ eeyan lo gbagbọ pe òógùn lo ma n mu ki ara rùn, sugbọn otitọ to wa nibẹ ni pe óògùn ara eniyan kii rùn rara. Oorun ti ko dara ma n wa lati àwọn ẹ̀yà ara bi ẹnu ati awọn ẹ̀yà mii. Ṣùgbọ́n ninu akọsilẹ yii, awọn òórùn to n jade lati awọ ara ni yoo jẹ afojusun wa. Ati bi kokoro aifojuri ṣe ma n jẹyọ ninu óògùn eniyan. Àwọn nkan to ma n fa òórùn ti ko dara 'body odour' ninu ara: Iwe iroyin imọ iṣegun oyinbo, British Medical News Today, sọ pe oorun yii ma n bẹ̀rẹ̀ lasiko ti eeyan ba ṣẹṣẹ n bàlágà, paapaa nitori awọn ayipada to n ba àwọn ẹ̀yà ara. Yatọ si eyi, o ṣe e ṣe ki awọn eeyan to sanra jù ati awọn to ni aisan bi itọ ṣuga ní oorun ti ko dara ninu ara wọn. Oorun buruku ma n jade ni ara nigba ti awọn kokoro aifojuri ba n la orisirisi ipele kọja, lati darí pinpin eroja PROTEIN to wa ninu òógùn, nibi ti o ti n ri oúnjẹ. Dokita Abubakar Mohammed, ti ileewosan Specialist Hospital, Maiduguri, sọ pe àwọn kokoro aifojuri to n gbe nibi to ba tutu ninu ara lo n fa ki òórùn buruku ma jade, kii ṣe óògùn fúnra rẹ. Idi ree ti awọn to ma n làá gùn pupọ ṣe ma n ni 'body odour'. Dokita Mohammed tun sọ pe jíjẹ awọn oúnjẹ bii galiiki, alubosa ati ata, le mu ki eeyan laagun ju bó ṣe yẹ. Bi o ṣe le dena ati ọna abayọ si 'body odour' Ọ̀pọ̀ eeyan ma n ni iriri 'body odour' ni àwọn ẹ̀yà ara wọn ti aṣọ bá bò - eyi to ma n fa óògùn ati ki aṣọ tutu. Dokita Abubakar sọ pe ọkan gboogi lara nkan to n fa "body odour" nìyẹn. Lati dena rẹ, awọn ọna ti awọn onímọ̀ ilera sọ ree: - Wiwẹ pẹlu omi to mọ ati ọṣẹ oloorun didun. Ki eeyan si fọ awọn ibi to le run bii ẹnu, abiya ati abẹ́ daadaa. - Wiwọ aṣọ to mọ- nitori ko si bi eeyan ṣe le wẹ̀ tó, ara rẹ yoo rùn to ba wọ aṣọ to dọti. Paapaa aṣọ bi awọtẹlẹ, pátá, ibọsẹ, sikẹẹti, kọmu ati aṣọ olooru. - Fifa irun ara - Ti irun ba kún ni àwọn ibi kan ninu ara, yoo fa óògùn, eyi to má n pada fi ààyè gba kokoro aifojuri to n fa òórùn buburu ninu ara. Nitori naa lo ṣe yẹ ki o fa irun ni awọn ẹ̀yà ara kan, lati le dena rẹ. - Lilo lọfinda - Lilo lọfinda loore-koore, ṣe pataki ninu igbesẹ didena oorun buburu. Yatọ si awọn nkan ti dokita sọ, o tun le lo àwọn nkan bí omi orombo wẹ́wẹ́ (lemon) lati fi òpin si oorun buburu ninu ara rẹ. Fi omi orombo naa pa awọn ibi to ba n run, saaju ki o to wẹ. O tun le fi alọọmu sinu omi iwẹ rẹ, to ba jẹ pe oorun ara rẹ pọ. Ṣùgbọ́n ti o ba ṣe gbogbo nkan wọn yii, ti oorun naa ko ba dinku tabi lọ patapata, tete lọ ri dokita. Idi ni pe ki eeyan ma laagun ju, ati ki oorun buruku ma jade ninu ara, le jẹ ami aisan bi itọ ṣuga, aisan kíndìnrín, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Body odour solution: Wo ǹkan tó ń fa 'body odour' àti bí o ṣè lè ṣẹ́gun rẹ̀ Àwọn onimọ sọ pe ọpọ eeyan lo gbagbọ pe òógùn lo ma n mu ki ara rùn, sugbọn otitọ to wa nibẹ ni pe óògùn ara eniyan kii rùn rara. Oorun ti ko dara ma n wa lati àwọn ẹ̀yà ara bi ẹnu ati awọn ẹ̀yà mii. Ṣùgbọ́n ninu akọsilẹ yii, awọn òórùn to n jade lati awọ ara ni yoo jẹ afojusun wa. Ati bi kokoro aifojuri ṣe ma n jẹyọ ninu óògùn eniyan. Àwọn nkan to ma n fa òórùn ti ko dara 'body odour' ninu ara: Iwe iroyin imọ iṣegun oyinbo, British Medical News Today, sọ pe oorun yii ma n bẹ̀rẹ̀ lasiko ti eeyan ba ṣẹṣẹ n bàlágà, paapaa nitori awọn ayipada to n ba àwọn ẹ̀yà ara. Yatọ si eyi, o ṣe e ṣe ki awọn eeyan to sanra jù ati awọn to ni aisan bi itọ ṣuga ní oorun ti ko dara ninu ara wọn. Oorun buruku ma n jade ni ara nigba ti awọn kokoro aifojuri ba n la orisirisi ipele kọja, lati darí pinpin eroja PROTEIN to wa ninu òógùn, nibi ti o ti n ri oúnjẹ. Dokita Abubakar Mohammed, ti ileewosan Specialist Hospital, Maiduguri, sọ pe àwọn kokoro aifojuri to n gbe nibi to ba tutu ninu ara lo n fa ki òórùn buruku ma jade, kii ṣe óògùn fúnra rẹ. Idi ree ti awọn to ma n làá gùn pupọ ṣe ma n ni 'body odour'. Dokita Mohammed tun sọ pe jíjẹ awọn oúnjẹ bii galiiki, alubosa ati ata, le mu ki eeyan laagun ju bó ṣe yẹ. Bi o ṣe le dena ati ọna abayọ si 'body odour' Ọ̀pọ̀ eeyan ma n ni iriri 'body odour' ni àwọn ẹ̀yà ara wọn ti aṣọ bá bò - eyi to ma n fa óògùn ati ki aṣọ tutu. Dokita Abubakar sọ pe ọkan gboogi lara nkan to n fa "body odour" nìyẹn. Lati dena rẹ, awọn ọna ti awọn onímọ̀ ilera sọ ree: - Wiwẹ pẹlu omi to mọ ati ọṣẹ oloorun didun. Ki eeyan si fọ awọn ibi to le run bii ẹnu, abiya ati abẹ́ daadaa. - Wiwọ aṣọ to mọ- nitori ko si bi eeyan ṣe le wẹ̀ tó, ara rẹ yoo rùn to ba wọ aṣọ to dọti. Paapaa aṣọ bi awọtẹlẹ, pátá, ibọsẹ, sikẹẹti, kọmu ati aṣọ olooru. - Fifa irun ara - Ti irun ba kún ni àwọn ibi kan ninu ara, yoo fa óògùn, eyi to má n pada fi ààyè gba kokoro aifojuri to n fa òórùn buburu ninu ara. Nitori naa lo ṣe yẹ ki o fa irun ni awọn ẹ̀yà ara kan, lati le dena rẹ. - Lilo lọfinda - Lilo lọfinda loore-koore, ṣe pataki ninu igbesẹ didena oorun buburu. Yatọ si awọn nkan ti dokita sọ, o tun le lo àwọn nkan bí omi orombo wẹ́wẹ́ (lemon) lati fi òpin si oorun buburu ninu ara rẹ. Fi omi orombo naa pa awọn ibi to ba n run, saaju ki o to wẹ. O tun le fi alọọmu sinu omi iwẹ rẹ, to ba jẹ pe oorun ara rẹ pọ. Ṣùgbọ́n ti o ba ṣe gbogbo nkan wọn yii, ti oorun naa ko ba dinku tabi lọ patapata, tete lọ ri dokita. Idi ni pe ki eeyan ma laagun ju, ati ki oorun buruku ma jade ninu ara, le jẹ ami aisan bi itọ ṣuga, aisan kíndìnrín, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
https://www.bbc.com/yoruba/61379653
2health
"Ẹsẹ̀ mí kẹ̀, ó dojú kọ ara wọn bíi pẹ́rẹ́gi, ìṣẹ́ abẹ kẹta ló mú kó nà padà"
Adebola Oluwole Dada jẹ obinrin kan ti ẹsẹ rẹ kẹ lati kekere, eyi ti wn n pe ni Bow leg. Ẹsẹ naa kẹ to bẹẹ gẹẹ debi pe wọn doju kọ ara wọn ni, to si maa n dun to ba n rin lọ. Nigba to ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn ipenija ati idẹyẹsi to koju nitori pe ẹsẹ rẹ kẹ sinu, Adebola salaye pe ẹlẹsẹ pẹrẹgi ni wn pe oun ni kekere. O fikun pe bi o tilẹ jẹ pe oun sisẹ abẹ lati na ẹsẹ naa nigba ti oun wa ni ọmọ ọdun mẹfa ati nigba ti oun sinru ilu NYSC tan, sibẹ ẹsẹ naa tun pada kẹ. Adebola ni o maa n dun oun nigba ti oun ba n rin lọ, ti ọpọ eeyan si n tẹju mọ oun. Amọ o salaye pe isoro naa di ohun itan lẹyin ti oun se igbeyawo, ti oun si bi gbogbo ọmọ ọmọ inu oun tan. O ni asiko yii ni oun pada lọ se isẹ abẹ ẹlẹẹkẹta, ki ẹsẹ mejeeji naa to na pada, ti inu oun si dun pupọ. Adebola, tii se osisẹ agbohunsafẹfẹ salaye pe lasiko ti oun n la isoro ẹsẹ oun mejeeji to kẹ naa kọja, oun ko jẹ ki irẹwẹsi de ba ọkan oun lati de ibi ti oun pinnu lati de nile aye. O wa n gba gbogbo awọn eeyan to n koju irufẹ isoro yii nimọran lati mase jẹ ki ipenija naa mu akude ba ọkan wọn , amọ ki wn pinnu lati de ibi giga ti wn fẹ.
"Ẹsẹ̀ mí kẹ̀, ó dojú kọ ara wọn bíi pẹ́rẹ́gi, ìṣẹ́ abẹ kẹta ló mú kó nà padà" Adebola Oluwole Dada jẹ obinrin kan ti ẹsẹ rẹ kẹ lati kekere, eyi ti wn n pe ni Bow leg. Ẹsẹ naa kẹ to bẹẹ gẹẹ debi pe wọn doju kọ ara wọn ni, to si maa n dun to ba n rin lọ. Nigba to ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn ipenija ati idẹyẹsi to koju nitori pe ẹsẹ rẹ kẹ sinu, Adebola salaye pe ẹlẹsẹ pẹrẹgi ni wn pe oun ni kekere. O fikun pe bi o tilẹ jẹ pe oun sisẹ abẹ lati na ẹsẹ naa nigba ti oun wa ni ọmọ ọdun mẹfa ati nigba ti oun sinru ilu NYSC tan, sibẹ ẹsẹ naa tun pada kẹ. Adebola ni o maa n dun oun nigba ti oun ba n rin lọ, ti ọpọ eeyan si n tẹju mọ oun. Amọ o salaye pe isoro naa di ohun itan lẹyin ti oun se igbeyawo, ti oun si bi gbogbo ọmọ ọmọ inu oun tan. O ni asiko yii ni oun pada lọ se isẹ abẹ ẹlẹẹkẹta, ki ẹsẹ mejeeji naa to na pada, ti inu oun si dun pupọ. Adebola, tii se osisẹ agbohunsafẹfẹ salaye pe lasiko ti oun n la isoro ẹsẹ oun mejeeji to kẹ naa kọja, oun ko jẹ ki irẹwẹsi de ba ọkan oun lati de ibi ti oun pinnu lati de nile aye. O wa n gba gbogbo awọn eeyan to n koju irufẹ isoro yii nimọran lati mase jẹ ki ipenija naa mu akude ba ọkan wọn , amọ ki wn pinnu lati de ibi giga ti wn fẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c9xl4gy85rgo
5sports
UFC248: Israel Adesanya ti fi ẹ̀ṣẹ́ yanjú Romero ní ìjà ẹ̀ṣẹ́ kíkàn
Abẹṣẹkubiojo ọmọ Naijiria ni, Iṣrael Adesanya ṣi ni ẹṣin iwaju ti gbogbo tẹyin n wo sare ni ere idaraya ẹṣẹ ati ipa kikan, iyẹn UFC248 ni ipele middlewight. Israel Adesanya to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun lorilẹede Naijiria fi agba han Yoel Romero ninu idajọ gbogbo awọn adajọ to mojuto ija naa. Ìròyin so pé láti igbà ti Yoel Romero ti n kopa nínú eré ìdaáraya abẹsẹ́ kù bi ojo, ko si ẹni to fi ojú rẹ̀ gbòlẹ̀ rìí, Sugbọ́n ní báyìí Isreal Adesanya fẹ́ tún ìtàn náà kọ. Bi o tilẹ jẹ wi pe ọpọ awọn onworan lo fẹhonu han pe ija naa ko dun bi awọn ṣe lero, sibẹ gbogbo awọn onidajs mẹtẹẹta to wa nikalẹ fun ija naa ni wọn gbe idajs kalẹ pe ọwọ Adesanya lo dun Romero julọ lasiko ija naa. Ninu ọrs to sọ lẹyin ija naa, Adesanya ṣalaye pe ija naa ko rọgbọ, ṣugbọn gbogbo ohun to yẹ ki oun ṣe lati bori ni oun ṣe. Pẹlu ija yii, Adesanya ti ja ija mọkandinlogun, o si ti bori gbogbo rẹ. Nibayii, ti Romero ti kuro, ọna la fun ija laarin Adesanya to wa loke tente atẹ igbelewọn awọn akanṣẹ ni ipele Middlewieght, ija ẹṣẹ ati ipa kikan UFC248 lati koju Paulo Costa to wa ni ipo keji lori atẹ naa. Pẹlu abajade ija naa, Romero ti padanu marun ninu ija mejidinlogun to ti ja, mẹtala ninu rẹ lo bori. O si tun yọju sita pe mẹrin ninu ija marun to ja sẹyin ni ṣisẹ-n-tẹle lo ti padanu bayii. Romero ni, "nṣe lo kan n sare kaakiri oju agbo ija" o fi kun un pe ija ajakuorogbo lawọn eeyan wa wo, ohun si ni wọn sanwo fun lati wo kaakiri agbaye.
UFC248: Israel Adesanya ti fi ẹ̀ṣẹ́ yanjú Romero ní ìjà ẹ̀ṣẹ́ kíkàn Abẹṣẹkubiojo ọmọ Naijiria ni, Iṣrael Adesanya ṣi ni ẹṣin iwaju ti gbogbo tẹyin n wo sare ni ere idaraya ẹṣẹ ati ipa kikan, iyẹn UFC248 ni ipele middlewight. Israel Adesanya to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun lorilẹede Naijiria fi agba han Yoel Romero ninu idajọ gbogbo awọn adajọ to mojuto ija naa. Ìròyin so pé láti igbà ti Yoel Romero ti n kopa nínú eré ìdaáraya abẹsẹ́ kù bi ojo, ko si ẹni to fi ojú rẹ̀ gbòlẹ̀ rìí, Sugbọ́n ní báyìí Isreal Adesanya fẹ́ tún ìtàn náà kọ. Bi o tilẹ jẹ wi pe ọpọ awọn onworan lo fẹhonu han pe ija naa ko dun bi awọn ṣe lero, sibẹ gbogbo awọn onidajs mẹtẹẹta to wa nikalẹ fun ija naa ni wọn gbe idajs kalẹ pe ọwọ Adesanya lo dun Romero julọ lasiko ija naa. Ninu ọrs to sọ lẹyin ija naa, Adesanya ṣalaye pe ija naa ko rọgbọ, ṣugbọn gbogbo ohun to yẹ ki oun ṣe lati bori ni oun ṣe. Pẹlu ija yii, Adesanya ti ja ija mọkandinlogun, o si ti bori gbogbo rẹ. Nibayii, ti Romero ti kuro, ọna la fun ija laarin Adesanya to wa loke tente atẹ igbelewọn awọn akanṣẹ ni ipele Middlewieght, ija ẹṣẹ ati ipa kikan UFC248 lati koju Paulo Costa to wa ni ipo keji lori atẹ naa. Pẹlu abajade ija naa, Romero ti padanu marun ninu ija mejidinlogun to ti ja, mẹtala ninu rẹ lo bori. O si tun yọju sita pe mẹrin ninu ija marun to ja sẹyin ni ṣisẹ-n-tẹle lo ti padanu bayii. Romero ni, "nṣe lo kan n sare kaakiri oju agbo ija" o fi kun un pe ija ajakuorogbo lawọn eeyan wa wo, ohun si ni wọn sanwo fun lati wo kaakiri agbaye.
https://www.bbc.com/yoruba/media-51788498
4religion
Deborah Samuel: "Kuran ni aṣáájú Hadith", bí ọ̀rọ̀ bá dàrú, Akeugbagold sọ ohun tí àá padà sí
"Lóótọ́, awọn aayaa igba ogun kan wa ti Hadith wọn sọkalẹ fun awọn Musulumi nigba naa lati ran wọn lọwọ, amọ ogun yẹn ti tan, Hadith ti alafia lo yẹ kẹẹ maa lo bayii". Gbajumọ oniwaasi nilu Ibadan, Sheikh Akeugbagold n sọ eyi lati da si ọrọ Deborah Samuel ti wọn sọ ni oko pa ti wọn tun dana sun laipẹ yii ni ilu Sokoto. "Mo ti ṣe waasi kan ninu eyi ti mo ti sọ awọn aaya to pọ lati fi jẹ kawọn eeyan mọ pe ko si ibi ti Ọlọhun ti sọ pe ki wọn sọ eeyan ni oko pa". Wọ́n gbé 'Póò ìtọ̀ àti igbẹ́’ tó ti já nídìí lé mi lórí lọ dànù l’Eko, pẹ̀lú òúnjẹ́ mi lọ́wọ́ mi - Ajirebi Láí ṣẹ̀ láí rò, wọ́n jó Ṣọ́ọ́ṣì mi pátápátá ní Sokoto, ìrírí mi rèé - Pasitọ ìjọ Celestial Adájọ́ 34 táa tán nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé 'Ẹ yẹgi fún un'! Ọkùnrin ẹni ọdún 42 gba ìdájọ́ ikú lẹ́yìn tó pa Ọba aládé l'Ekiti Àwọn Mùsùlùmí tó ṣekúpa Deborah nítori ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kò ní wọ párádísè - Sheikh Gumi Wo àwon ìròyìn òfégè nípa ikú Deborah Ṣamuel àti ìkọlù sí Bishop Kukah Ẹni ọdún mẹ́rin ni mo bẹ̀rẹ̀ Kéwú, 1967 ni mo ṣe wòlímọ̀, mo lè kéwú láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin- Tunde Bakare 'Ọ̀pọ̀ ìgbà l'èmí gan fẹ́ du àwọn ipò òṣèlú kan lọ́dún 2015, 2019, àmọ́ mo tẹ 'slow' torí bàbà mi, Akala náà ń jáde' O tọka awọn eeyan si apa ibi kan ninu Kuran to ti ni Ọlọhun ni "Anọbi, oo mọọ gbọ ohun ti yoo ba ọ ninu jẹ o, ṣe suuru gẹgẹ bi awọn ti wọn ti lọ si waju ṣe ṣe". Bakan naa lo tun ka ibomii, to tun ka ibomii, to si tun ka ibomii, to ni "nkankan naa ni Ọlọhun sọ nibẹ pe Anọbi yoo maa gbọ ohun ti yoo ba a ninu jẹ ni. "Kurani ni 'Primary, Hadith ni Secondary', tọrọ ba daru, Kuran laa pada si" O ni nkan ti awọn kan n sọ ninu itan pe Anọbi dajọ iku fun arakunrin kan to bu u ri, "ti Anọbi ba ṣe bẹẹ, a jẹ pe Anọbi tako Kuran ni, Anọbi ko si ki n ṣe ika". O ni ẹnikan ti dojukọ Anọbi ri pe "Were" ni amọ ti Anọbi daa lohun lọna to tọ ninu Kuran. Láti ìgbà tí wọ́n ti bí mi, kò sí obìnrin tí mo kọnu ìfẹ́ sí tí kò gbà fún mi -Efuoma Amos Àwọn ọlọ́kadà dáná sun 'Sound engineer' l'Eko lẹ́yìn àríyànjiyàn lórí ₦100 Kà nípa àwọn mínísítà mẹ́wàá tó kọ̀wé fipò sílẹ̀ lábẹ ìjọba Ààrẹ Buhari Àwọn àgbébọn ti tú olóyún tó wà lára àwọn awakọ̀ reluwé Abuja sí Kaduna tí wọ́n jí gbé sílẹ̀ Akeugbagold ni Islam kii ṣe ẹsin ika ko si si ninu Kuran rara iwa ti awọn kan hu nilu Sokoto. O ni ki wọn lọ wadi ohun ti Arabinrin Deborah sọ daadaa, iwa ika bii pe awujọ ẹran la n gbe ni wọn hu gbaa. "Ẹ ma sọ Islam lorukọ ti ko jẹẹ".
Deborah Samuel: "Kuran ni aṣáájú Hadith", bí ọ̀rọ̀ bá dàrú, Akeugbagold sọ ohun tí àá padà sí "Lóótọ́, awọn aayaa igba ogun kan wa ti Hadith wọn sọkalẹ fun awọn Musulumi nigba naa lati ran wọn lọwọ, amọ ogun yẹn ti tan, Hadith ti alafia lo yẹ kẹẹ maa lo bayii". Gbajumọ oniwaasi nilu Ibadan, Sheikh Akeugbagold n sọ eyi lati da si ọrọ Deborah Samuel ti wọn sọ ni oko pa ti wọn tun dana sun laipẹ yii ni ilu Sokoto. "Mo ti ṣe waasi kan ninu eyi ti mo ti sọ awọn aaya to pọ lati fi jẹ kawọn eeyan mọ pe ko si ibi ti Ọlọhun ti sọ pe ki wọn sọ eeyan ni oko pa". Wọ́n gbé 'Póò ìtọ̀ àti igbẹ́’ tó ti já nídìí lé mi lórí lọ dànù l’Eko, pẹ̀lú òúnjẹ́ mi lọ́wọ́ mi - Ajirebi Láí ṣẹ̀ láí rò, wọ́n jó Ṣọ́ọ́ṣì mi pátápátá ní Sokoto, ìrírí mi rèé - Pasitọ ìjọ Celestial Adájọ́ 34 táa tán nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé 'Ẹ yẹgi fún un'! Ọkùnrin ẹni ọdún 42 gba ìdájọ́ ikú lẹ́yìn tó pa Ọba aládé l'Ekiti Àwọn Mùsùlùmí tó ṣekúpa Deborah nítori ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kò ní wọ párádísè - Sheikh Gumi Wo àwon ìròyìn òfégè nípa ikú Deborah Ṣamuel àti ìkọlù sí Bishop Kukah Ẹni ọdún mẹ́rin ni mo bẹ̀rẹ̀ Kéwú, 1967 ni mo ṣe wòlímọ̀, mo lè kéwú láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin- Tunde Bakare 'Ọ̀pọ̀ ìgbà l'èmí gan fẹ́ du àwọn ipò òṣèlú kan lọ́dún 2015, 2019, àmọ́ mo tẹ 'slow' torí bàbà mi, Akala náà ń jáde' O tọka awọn eeyan si apa ibi kan ninu Kuran to ti ni Ọlọhun ni "Anọbi, oo mọọ gbọ ohun ti yoo ba ọ ninu jẹ o, ṣe suuru gẹgẹ bi awọn ti wọn ti lọ si waju ṣe ṣe". Bakan naa lo tun ka ibomii, to tun ka ibomii, to si tun ka ibomii, to ni "nkankan naa ni Ọlọhun sọ nibẹ pe Anọbi yoo maa gbọ ohun ti yoo ba a ninu jẹ ni. "Kurani ni 'Primary, Hadith ni Secondary', tọrọ ba daru, Kuran laa pada si" O ni nkan ti awọn kan n sọ ninu itan pe Anọbi dajọ iku fun arakunrin kan to bu u ri, "ti Anọbi ba ṣe bẹẹ, a jẹ pe Anọbi tako Kuran ni, Anọbi ko si ki n ṣe ika". O ni ẹnikan ti dojukọ Anọbi ri pe "Were" ni amọ ti Anọbi daa lohun lọna to tọ ninu Kuran. Láti ìgbà tí wọ́n ti bí mi, kò sí obìnrin tí mo kọnu ìfẹ́ sí tí kò gbà fún mi -Efuoma Amos Àwọn ọlọ́kadà dáná sun 'Sound engineer' l'Eko lẹ́yìn àríyànjiyàn lórí ₦100 Kà nípa àwọn mínísítà mẹ́wàá tó kọ̀wé fipò sílẹ̀ lábẹ ìjọba Ààrẹ Buhari Àwọn àgbébọn ti tú olóyún tó wà lára àwọn awakọ̀ reluwé Abuja sí Kaduna tí wọ́n jí gbé sílẹ̀ Akeugbagold ni Islam kii ṣe ẹsin ika ko si si ninu Kuran rara iwa ti awọn kan hu nilu Sokoto. O ni ki wọn lọ wadi ohun ti Arabinrin Deborah sọ daadaa, iwa ika bii pe awujọ ẹran la n gbe ni wọn hu gbaa. "Ẹ ma sọ Islam lorukọ ti ko jẹẹ".
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61462142
3politics
How Abiodun Oyebanji won in Ekiti: Fídíò bí Oyebanji ṣe la Oni, Kolawole mọ́lẹ̀ rèé
Kedere ni oju awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu kọọkan la kalẹ ni ibudo ajọ eleto idibo INEC to wa ni ipinlẹ Ekiti nibi ti wọn ti ka gbogbo esi idibo ijọba ibilẹ kọọkan. Oru mọjumọ oni si ni wọn pari rẹ gẹgẹ baa ṣe n mu awọn esi idibo naa jade fun yin lọlọkan o jọkan. Ẹwẹ, ni kete ti wọn ka awọn esi idibo naa tan ni Ọjọgbọn Fasiti ti ajọ INEC gba lati wa ṣe alamojuto agba nibi idibo naa, Ọjọgbọn Kayode Adebowale kede ẹni to jawe olubori. INEC kéde Abiodun Oyebanji pé òun ló mókè nínú ìbò gómìnà l‘Ekiti Máàpù tó ṣàlàyé gbogbo èsì ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti rèé O ṣalaye bi ohun gbogbo ṣe lọ ni ibamu ofin ajọ INEC Fídíò bí Oyebanji ṣe la Segun Oni ti SDP ati Bisi Kolawole ti PDP mọ́lẹ̀ rèé.
How Abiodun Oyebanji won in Ekiti: Fídíò bí Oyebanji ṣe la Oni, Kolawole mọ́lẹ̀ rèé Kedere ni oju awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu kọọkan la kalẹ ni ibudo ajọ eleto idibo INEC to wa ni ipinlẹ Ekiti nibi ti wọn ti ka gbogbo esi idibo ijọba ibilẹ kọọkan. Oru mọjumọ oni si ni wọn pari rẹ gẹgẹ baa ṣe n mu awọn esi idibo naa jade fun yin lọlọkan o jọkan. Ẹwẹ, ni kete ti wọn ka awọn esi idibo naa tan ni Ọjọgbọn Fasiti ti ajọ INEC gba lati wa ṣe alamojuto agba nibi idibo naa, Ọjọgbọn Kayode Adebowale kede ẹni to jawe olubori. INEC kéde Abiodun Oyebanji pé òun ló mókè nínú ìbò gómìnà l‘Ekiti Máàpù tó ṣàlàyé gbogbo èsì ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti rèé O ṣalaye bi ohun gbogbo ṣe lọ ni ibamu ofin ajọ INEC Fídíò bí Oyebanji ṣe la Segun Oni ti SDP ati Bisi Kolawole ti PDP mọ́lẹ̀ rèé.
https://www.bbc.com/yoruba/61855958
1entertainment
Baba Ijesha case: Yomi Fabiyi ní òun ṣetán láti pàdánù gbogbo dúkìá òun sórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn
Pẹlu bi awọn eeyan ti ṣe n reti itusilẹ gbajumọ oṣere, Baba Ijesha, lẹyin ti adajọ gba beeli rẹ, ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ to ja fitafita fun gbigba oniduro rẹ, Ọgbẹni Yọmi Fabiyi tun ti sọrọ soke. Yomi Fabiyi lasiko yii, ti wa fi ohun ranṣẹ si gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu pe ko ri daju pe ibọwọ fofin ati ẹtọ ọmọniyan tubọ gbẹrẹgẹjigẹ nipinlẹ Eko. Ninu ọrọ kan to kọ soju opo Instagram rẹ, Yọmi Fabiyi kan sara si Gomina Sanwo-Olu fun gbigbe ibọwọ fun ofin ati ẹtọ ọmọniyan soke ni ipinlẹ Eko. Fabiyi ni "ara awọn afihan iṣejọba awarawa tootọ ati itanna iṣejọba igbalode ti ipinlẹ tabi orilẹede to fẹ goke agba nilo ree." Yọmi Fabiyi, to ni oun ko kabamọ pe oun dibo fun Sanwo-Olu, wa rọ gomina ipinlẹ Eko naa lati tẹẹ mọ awọn ileeṣẹ eto iroyin ati eto idajọ ni ipinlẹ Eko leti, nipa pataki idanilẹkọ nipa ẹtọ ọmọniyan lawọn ileewe gbogbo. Bakan naa lo tun pe fun agbekalẹ abẹwo oloṣooṣu sawọn ahamọ ọlọpaa gbogbo, ki wọn si maa fi iya to ba tọ jẹ awọn ọga ọlọpaa gbogbo ati olori ẹka ọlọpaa, to ba tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ. O fi kun un pe, oun ṣetan lati padanu gbogbo ohun ti oun ni lori ibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria. Yoruba ma n sọ pe ka sọrọ ka ba bẹ ẹ, ni iyi ọmọ eniyan. Bẹẹ gan-an ni oṣerekunrin,Yomi Fabiyi ṣe ni owurọ Ọjọru, ọjọ kejila, oṣu Karun-un, pẹlu bo ṣe mu ipinnu rẹ lati ṣe iwọde nitori ọrọ Baba Ijẹsha ṣẹ. Lati bi ọsẹ kan sẹyin ni Fabiyi ti n polongo lori ayelujara pe, oun yoo ṣe iwọde tako bi awọn ọlọpaa ko ṣe gba beeli akẹẹgbẹ rẹ. Ẹsun fifi ipa ba majesin lopọ ni wọn fi kan Baba Ijẹsha. Ninu awọn ikede ti Yomi Fabiyi ti n sẹ sẹyin lori iwọde naa lo ti n sọ pe o tako ofin Naijiria ati ẹtọ ọmọniyan, bi afurasi naa si ṣe wa ni ahamọ ọlọpaa. O ni alakalẹ ofin ni pe afurasi ko gbọdọ kọja wakati mejidinlaadọta lọ ni atimọle, fun ẹsun ti wọn le gba beeli rẹ . Ẹni tó bá ní láàkàyè, a mọ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, àwà ti kọ lẹ́tà, èsì t'Ọ́lọ́pàá sì fún wa rèé - Yomi Fabiyi Iṣẹ́ tíátà tí bájẹ́, ẹni ẹlẹ́ni ló ń jẹ iṣẹ́ wa - Yomi Fabiyi Ẹni tó bá ní láàkàyè, a mọ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, àwà ti kọ lẹ́tà, èsì t'Ọ́lọ́pàá sì fún wa rèé - Yomi Fabiyi Lizzy Anjorin yóò jàre Toyin Abraham tó bá jẹ́ pé wọ́n lọ sílé ẹjọ́ - Yomi Fabiyi Botilẹ jẹ pe aago mẹwaa owurọ ni Ọgbẹni Fabiyi kede pe ki awọn to fẹ ẹ darapọ mọ iwọde naa pade oun ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n wadii ẹsun ọdaran, to wa ni Panti, Yaba, nilu Eko, ni nkan bi aago mẹjọ ni oun fun'ra rẹ ti bẹrẹ iwọde. Ninu fidio kan to fi sori ayeluajara, ni a ti ri Yomi, ati gende ọkunrin bi i mẹrin, ti wọn jọ kọwọrin lọ sibẹ. Yomi ti o n fun'ra rẹ wọ aṣọ dudu, ibori dudu lo sọ ọrọ apilẹsọ pe o yẹ ki awọn ọdọ Naijiria dide fun nkan to tọ. O ni kii ṣe pe o n sọ pe ki wọn o tu Baba Ijẹsha silẹ, tabi ma gbe e lọ sile ẹjọ. "Nkan ti mo n ja fun ni pe ki wọn o gba beeli rẹ, nitori pe wọn n fi akoko rẹ ṣofo ni ahamọ." Oriṣiriṣi akọle si ni wọn gbe dani. Ninu awọn akọle naa ni wọn kọ awọn ọrọ si lati fi ẹhonu wọn han pe 'iwa titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ ni awọn ọlọpaa n hu'. Awọn akọle miran n fi ẹsun kan pe awọn kan ti leri lati pa Baba Ijẹsha to ba fi kuro ni ahamọ. Bi awọn ọmọ ẹyin Yomi ṣe n na awọn akọle naa soke ni kọọkan, l'oun naa n kà to si n ṣe alaye l'ẹkunrẹrẹ lori nkan ti awọn akọle naa duro fun.
Baba Ijesha case: Yomi Fabiyi ní òun ṣetán láti pàdánù gbogbo dúkìá òun sórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn Pẹlu bi awọn eeyan ti ṣe n reti itusilẹ gbajumọ oṣere, Baba Ijesha, lẹyin ti adajọ gba beeli rẹ, ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ to ja fitafita fun gbigba oniduro rẹ, Ọgbẹni Yọmi Fabiyi tun ti sọrọ soke. Yomi Fabiyi lasiko yii, ti wa fi ohun ranṣẹ si gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu pe ko ri daju pe ibọwọ fofin ati ẹtọ ọmọniyan tubọ gbẹrẹgẹjigẹ nipinlẹ Eko. Ninu ọrọ kan to kọ soju opo Instagram rẹ, Yọmi Fabiyi kan sara si Gomina Sanwo-Olu fun gbigbe ibọwọ fun ofin ati ẹtọ ọmọniyan soke ni ipinlẹ Eko. Fabiyi ni "ara awọn afihan iṣejọba awarawa tootọ ati itanna iṣejọba igbalode ti ipinlẹ tabi orilẹede to fẹ goke agba nilo ree." Yọmi Fabiyi, to ni oun ko kabamọ pe oun dibo fun Sanwo-Olu, wa rọ gomina ipinlẹ Eko naa lati tẹẹ mọ awọn ileeṣẹ eto iroyin ati eto idajọ ni ipinlẹ Eko leti, nipa pataki idanilẹkọ nipa ẹtọ ọmọniyan lawọn ileewe gbogbo. Bakan naa lo tun pe fun agbekalẹ abẹwo oloṣooṣu sawọn ahamọ ọlọpaa gbogbo, ki wọn si maa fi iya to ba tọ jẹ awọn ọga ọlọpaa gbogbo ati olori ẹka ọlọpaa, to ba tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ. O fi kun un pe, oun ṣetan lati padanu gbogbo ohun ti oun ni lori ibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria. Yoruba ma n sọ pe ka sọrọ ka ba bẹ ẹ, ni iyi ọmọ eniyan. Bẹẹ gan-an ni oṣerekunrin,Yomi Fabiyi ṣe ni owurọ Ọjọru, ọjọ kejila, oṣu Karun-un, pẹlu bo ṣe mu ipinnu rẹ lati ṣe iwọde nitori ọrọ Baba Ijẹsha ṣẹ. Lati bi ọsẹ kan sẹyin ni Fabiyi ti n polongo lori ayelujara pe, oun yoo ṣe iwọde tako bi awọn ọlọpaa ko ṣe gba beeli akẹẹgbẹ rẹ. Ẹsun fifi ipa ba majesin lopọ ni wọn fi kan Baba Ijẹsha. Ninu awọn ikede ti Yomi Fabiyi ti n sẹ sẹyin lori iwọde naa lo ti n sọ pe o tako ofin Naijiria ati ẹtọ ọmọniyan, bi afurasi naa si ṣe wa ni ahamọ ọlọpaa. O ni alakalẹ ofin ni pe afurasi ko gbọdọ kọja wakati mejidinlaadọta lọ ni atimọle, fun ẹsun ti wọn le gba beeli rẹ . Ẹni tó bá ní láàkàyè, a mọ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, àwà ti kọ lẹ́tà, èsì t'Ọ́lọ́pàá sì fún wa rèé - Yomi Fabiyi Iṣẹ́ tíátà tí bájẹ́, ẹni ẹlẹ́ni ló ń jẹ iṣẹ́ wa - Yomi Fabiyi Ẹni tó bá ní láàkàyè, a mọ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, àwà ti kọ lẹ́tà, èsì t'Ọ́lọ́pàá sì fún wa rèé - Yomi Fabiyi Lizzy Anjorin yóò jàre Toyin Abraham tó bá jẹ́ pé wọ́n lọ sílé ẹjọ́ - Yomi Fabiyi Botilẹ jẹ pe aago mẹwaa owurọ ni Ọgbẹni Fabiyi kede pe ki awọn to fẹ ẹ darapọ mọ iwọde naa pade oun ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n wadii ẹsun ọdaran, to wa ni Panti, Yaba, nilu Eko, ni nkan bi aago mẹjọ ni oun fun'ra rẹ ti bẹrẹ iwọde. Ninu fidio kan to fi sori ayeluajara, ni a ti ri Yomi, ati gende ọkunrin bi i mẹrin, ti wọn jọ kọwọrin lọ sibẹ. Yomi ti o n fun'ra rẹ wọ aṣọ dudu, ibori dudu lo sọ ọrọ apilẹsọ pe o yẹ ki awọn ọdọ Naijiria dide fun nkan to tọ. O ni kii ṣe pe o n sọ pe ki wọn o tu Baba Ijẹsha silẹ, tabi ma gbe e lọ sile ẹjọ. "Nkan ti mo n ja fun ni pe ki wọn o gba beeli rẹ, nitori pe wọn n fi akoko rẹ ṣofo ni ahamọ." Oriṣiriṣi akọle si ni wọn gbe dani. Ninu awọn akọle naa ni wọn kọ awọn ọrọ si lati fi ẹhonu wọn han pe 'iwa titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ ni awọn ọlọpaa n hu'. Awọn akọle miran n fi ẹsun kan pe awọn kan ti leri lati pa Baba Ijẹsha to ba fi kuro ni ahamọ. Bi awọn ọmọ ẹyin Yomi ṣe n na awọn akọle naa soke ni kọọkan, l'oun naa n kà to si n ṣe alaye l'ẹkunrẹrẹ lori nkan ti awọn akọle naa duro fun.
https://www.bbc.com/yoruba/awon-iroyin-miran-57085273
2health
Penis size by Dr Shanna Swan: Kí ló ń fa kí ǹkan ọmọkùnrin yorò?
Onimọ Sayẹnsi nipa ọrọ ayika ti fi hande pe nkan ọmọ ọkunrin eeyan maa n yoro ti awọn agbegbe rẹ ko si ni ṣara jọ nitori ti ayika eeyan. Dokita Shanna Swan sọ ninu iwe tuntun rẹ to kọ ti akọle rẹ n jẹ "Count Down" sọ pe ọmọ eniyan n doju kọ iṣoro iloyun ati ibimọ latari kẹmika kan ti wọn n pe ni "phthalates" to n fa ki wọn bi ọmọ ikoko pẹlu nkan kunrin tabi obinrin ti ko ṣara jọ daadaa. Ninu iwe naa, arabinrin Shanna ṣagbeyẹwo bi wọn ṣe n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iye atọ ọmọkunrin to n jade eyi to maa ṣakoba fun idagbasoke ilana ibimọ ọkunrin ati obinrin to si n ko ọjọ iwaju sinu ewu. Latari idọti ayika nkan ọmọkunrin tabi obinrin yii, awọn ọmọ ti wọn n bi ti nkan ọmọkunrin wọn kere ti n pọ sii. Iwadi Dokita Swan fihan gẹgẹ bi wọn ṣe fi awọn ekute ṣe ayẹwo kẹmika phthalate ọhun ti wọn si rii pe nigba ti wọn fi ṣi ara ọmọ oyun inu wọn si kẹmika naa, o da bii pe wọn yoo bi awọn ọmọ naa pẹlu nkan ọmọ ọkunrin konkolo. O wadii pe awọn ikoko ọkunrin ti ara wọn ba ni nkan ṣe pẹlu phthalates ninu oyun maa n ni awọn nkan to rọ mọ nkan ọmọkunrin kukuru. Kẹmika naa ni iṣẹ to n ṣe ni awọn ileeṣẹ ti wọn fi n mu ki ike rọba fẹlẹ sii ṣugbọn Dokita Swan ni awọn kẹmika naa ti n wọ inu awọn nkan iṣere ati ounjẹ to si n ṣakoba fun idagbasoke eeyan. Phthalates jẹ akojọpọ awọn kẹmika ti wọn fi ṣe nkan elo pupọ bii iṣere ọmọde, nkan ti wọn n lẹ mọlẹ, lẹ m ogiri, ọṣẹ, ọili, nkan iko ounjẹ si, awn nkan ilera, apo ẹjẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ. Wọn maa n lo o ninu awọn oun elo aṣaraloge bii kẹmika ti wọn fi n nu eekana, iparun, ipa abiya lẹ́yìn fifa irun ibẹ, ọṣẹ iwẹ, ọṣẹ ifọrun, lọfinda ati bẹẹ lọ. Wọn maa n lo o lati mu polyvinyl chloride, iyẹn ike rọba ti wọn si tun nlo bii amu nkan yọ ninu awọn ipara. Ninu akọsilẹ iwe kan ti awọn onimọ Sayẹnsi tun fi si ori ayelujara Medical news website, wọn ṣalaye awọn idi mii to fi le mu nkan ọmọ ọkunrin kere sii. Ki nkan ọmọkunrin maa kere wọpọ paapaa bi awọn ọkunrin ba ṣe n dagba si ṣugbọn awọn idi mii naa wa to le fi yoro. Bi ọkunrin ba ṣe n dagba sii, awọn nkan ọlọra to wa ninu ara wn a maa ṣa ara jọ ninu awọn nkan to maa n pin ẹjẹ kaakiri ara yoo si mu ki eyi dinku. eleyi maa mu ki awọn sẹẹli iṣan ara to wa nibi ohun to n mu nkan ọmọ ọkunrin le bẹrẹ si ni ṣaarẹ. Awọn tuubu to n mu nkan ọmọkunrin le maa ṣiṣẹ karakara ti ẹjẹ ba n wọ ibẹ daadaa torinaa bi ẹjẹ naa ba ti dinku, o tumọ si pe nkan ọkunrin naa ko ni maa fibẹẹ le ni gbogbo igba. Ipa ti sisanra n ko paapaa ni agbegbe ikùn jẹ pabanbari fun ọpọlọpọ awọn ọkunrin bi wọn ba ṣe n dagba. Bo til jẹ pe nkan ọmọkunrin le fara han bii kekere nitori sisanra, amọ o le ma yoro. idi ti yoo fi jọ pe o kere ni pe ara ogiri ikun ni ibẹrẹ nkan ọmọkunrin wa bi ikun ba si ti n tobi sii, yoo fa nkan ọmọkunrin naa sinu. Bi eeyan ba wa jo lara, nkan ọmọkunrin rẹ yoo pada bọ sipo ati bo ṣe tobi si tẹlẹ. Iwadii kan ninu Journal of Impotence Research fihan pe bi ọkunrin ba ni aisan jẹjẹrẹ abẹ, ti wọn si fẹ ṣe iṣẹ abẹ eyi ti wọn n pe ni radical prostatectomy, o lee ni iriri ki nkan ọmọkunrin rẹ kere Awọn oogun kan wa to lee fa ki nkan ọmọkunrin kere. Awọn oogun bii Adderall ti wọn maa n lo fun ẹni ti iṣe féfé rẹ ba ti kọja ala, bakan naa awọn oogun to n wo iporuru ọkan san, oogun to n wo arun ọpọlọ san atawọn oogun mii ti dokita ba pe fun itọju abẹ wiwu. Ni ọdun 1998, fasiti oniṣegun ti Boston ṣe ayẹwo nkan awọn ọkunrin igba to dide duro tandi. Abajade ayẹwo naa fihan pe, awọn to n mu siga, ti nkan ọmọkunrin wọn ba dide, o maa n kuru ju ti ẹni ti ko mu siga lọ. Idi si ni pe kẹmika to n jade lasiko ti wọn ba n fa siga simu lee ṣe ọna ti ẹjọ n gba lọ inu nkan ọmọ ọkunrin leṣe. O si lee dena ki ẹjẹ kun inu nkan ọmọkunrin naa eyi ti yoo fi dide. Lai wo ti miu ara ya ati ipa to n ko ninu ọpọlọ, bi ohun to n pin ẹjẹ kiri ba ti bajẹ, nkan ọmọkunrin ko le duro ko si ni le tandi.
Penis size by Dr Shanna Swan: Kí ló ń fa kí ǹkan ọmọkùnrin yorò? Onimọ Sayẹnsi nipa ọrọ ayika ti fi hande pe nkan ọmọ ọkunrin eeyan maa n yoro ti awọn agbegbe rẹ ko si ni ṣara jọ nitori ti ayika eeyan. Dokita Shanna Swan sọ ninu iwe tuntun rẹ to kọ ti akọle rẹ n jẹ "Count Down" sọ pe ọmọ eniyan n doju kọ iṣoro iloyun ati ibimọ latari kẹmika kan ti wọn n pe ni "phthalates" to n fa ki wọn bi ọmọ ikoko pẹlu nkan kunrin tabi obinrin ti ko ṣara jọ daadaa. Ninu iwe naa, arabinrin Shanna ṣagbeyẹwo bi wọn ṣe n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iye atọ ọmọkunrin to n jade eyi to maa ṣakoba fun idagbasoke ilana ibimọ ọkunrin ati obinrin to si n ko ọjọ iwaju sinu ewu. Latari idọti ayika nkan ọmọkunrin tabi obinrin yii, awọn ọmọ ti wọn n bi ti nkan ọmọkunrin wọn kere ti n pọ sii. Iwadi Dokita Swan fihan gẹgẹ bi wọn ṣe fi awọn ekute ṣe ayẹwo kẹmika phthalate ọhun ti wọn si rii pe nigba ti wọn fi ṣi ara ọmọ oyun inu wọn si kẹmika naa, o da bii pe wọn yoo bi awọn ọmọ naa pẹlu nkan ọmọ ọkunrin konkolo. O wadii pe awọn ikoko ọkunrin ti ara wọn ba ni nkan ṣe pẹlu phthalates ninu oyun maa n ni awọn nkan to rọ mọ nkan ọmọkunrin kukuru. Kẹmika naa ni iṣẹ to n ṣe ni awọn ileeṣẹ ti wọn fi n mu ki ike rọba fẹlẹ sii ṣugbọn Dokita Swan ni awọn kẹmika naa ti n wọ inu awọn nkan iṣere ati ounjẹ to si n ṣakoba fun idagbasoke eeyan. Phthalates jẹ akojọpọ awọn kẹmika ti wọn fi ṣe nkan elo pupọ bii iṣere ọmọde, nkan ti wọn n lẹ mọlẹ, lẹ m ogiri, ọṣẹ, ọili, nkan iko ounjẹ si, awn nkan ilera, apo ẹjẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ. Wọn maa n lo o ninu awọn oun elo aṣaraloge bii kẹmika ti wọn fi n nu eekana, iparun, ipa abiya lẹ́yìn fifa irun ibẹ, ọṣẹ iwẹ, ọṣẹ ifọrun, lọfinda ati bẹẹ lọ. Wọn maa n lo o lati mu polyvinyl chloride, iyẹn ike rọba ti wọn si tun nlo bii amu nkan yọ ninu awọn ipara. Ninu akọsilẹ iwe kan ti awọn onimọ Sayẹnsi tun fi si ori ayelujara Medical news website, wọn ṣalaye awọn idi mii to fi le mu nkan ọmọ ọkunrin kere sii. Ki nkan ọmọkunrin maa kere wọpọ paapaa bi awọn ọkunrin ba ṣe n dagba si ṣugbọn awọn idi mii naa wa to le fi yoro. Bi ọkunrin ba ṣe n dagba sii, awọn nkan ọlọra to wa ninu ara wn a maa ṣa ara jọ ninu awọn nkan to maa n pin ẹjẹ kaakiri ara yoo si mu ki eyi dinku. eleyi maa mu ki awọn sẹẹli iṣan ara to wa nibi ohun to n mu nkan ọmọ ọkunrin le bẹrẹ si ni ṣaarẹ. Awọn tuubu to n mu nkan ọmọkunrin le maa ṣiṣẹ karakara ti ẹjẹ ba n wọ ibẹ daadaa torinaa bi ẹjẹ naa ba ti dinku, o tumọ si pe nkan ọkunrin naa ko ni maa fibẹẹ le ni gbogbo igba. Ipa ti sisanra n ko paapaa ni agbegbe ikùn jẹ pabanbari fun ọpọlọpọ awọn ọkunrin bi wọn ba ṣe n dagba. Bo til jẹ pe nkan ọmọkunrin le fara han bii kekere nitori sisanra, amọ o le ma yoro. idi ti yoo fi jọ pe o kere ni pe ara ogiri ikun ni ibẹrẹ nkan ọmọkunrin wa bi ikun ba si ti n tobi sii, yoo fa nkan ọmọkunrin naa sinu. Bi eeyan ba wa jo lara, nkan ọmọkunrin rẹ yoo pada bọ sipo ati bo ṣe tobi si tẹlẹ. Iwadii kan ninu Journal of Impotence Research fihan pe bi ọkunrin ba ni aisan jẹjẹrẹ abẹ, ti wọn si fẹ ṣe iṣẹ abẹ eyi ti wọn n pe ni radical prostatectomy, o lee ni iriri ki nkan ọmọkunrin rẹ kere Awọn oogun kan wa to lee fa ki nkan ọmọkunrin kere. Awọn oogun bii Adderall ti wọn maa n lo fun ẹni ti iṣe féfé rẹ ba ti kọja ala, bakan naa awọn oogun to n wo iporuru ọkan san, oogun to n wo arun ọpọlọ san atawọn oogun mii ti dokita ba pe fun itọju abẹ wiwu. Ni ọdun 1998, fasiti oniṣegun ti Boston ṣe ayẹwo nkan awọn ọkunrin igba to dide duro tandi. Abajade ayẹwo naa fihan pe, awọn to n mu siga, ti nkan ọmọkunrin wọn ba dide, o maa n kuru ju ti ẹni ti ko mu siga lọ. Idi si ni pe kẹmika to n jade lasiko ti wọn ba n fa siga simu lee ṣe ọna ti ẹjọ n gba lọ inu nkan ọmọ ọkunrin leṣe. O si lee dena ki ẹjẹ kun inu nkan ọmọkunrin naa eyi ti yoo fi dide. Lai wo ti miu ara ya ati ipa to n ko ninu ọpọlọ, bi ohun to n pin ẹjẹ kiri ba ti bajẹ, nkan ọmọkunrin ko le duro ko si ni le tandi.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-56519998
3politics
Operation Amotekun: Amọ̀tẹ́kùn ṣetán láti gbérasọ, fọ́ọ̀mù ìgbaniṣíṣẹ́ ti dé!
Ohun to ba ti ya kan, kii pẹ mọ, fọọmu igbaniṣiṣẹ fun ẹṣọ alaabo lawọn ipinlẹ Yoruba, Amọtẹkun yoo jade lọsẹ to n bọ. Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lo fọrọ yii lede lati ẹnu oludamọran rẹ lori ọrọ aabo, Alhaji Jimoh Dojumo. Gomina Akeredolu ṣalaye pe gbogbo eto lo ti to bayii lati gbe fọọmu naa sita. ''Awọn ọba alaye atawọn olori awujọ ni yoo ṣe oniduro fawọn eeyan wọn to ba fẹ darapọ mọ ẹṣọ alaabo Amọtẹkun,'' Akeredolu lo ṣalaye bẹẹ. Laipẹ yi ni awọn gomina guusu iwọ oorun ṣepade pẹlu igbakeji aarẹ, Yemi Oṣibajo ati agbẹjọro agba ni Naijiria, Abubakar Malami lati sọ asọyepọ lori eto naa. Malami ti kọkọ sọ pe, eto Amọtẹkun tawọn gomina ipinlẹ Yoruba gbe kale ko si ninu iwe ofin Naijiria. Ọpọ awọn ilumọọka agbẹjọro atawọn ajafẹtọ omoniyan lo ti ṣatilẹyin fun eto Amọtẹkun lẹyin ti tako agbekalẹ eto naa. Ọjọ kẹsan an oṣu kinni lawọn gomina ilẹ Yoruba ṣe agbekalẹ Amọtẹkun ni olu ilu ipinlẹ Oyo, Ibadan.
Operation Amotekun: Amọ̀tẹ́kùn ṣetán láti gbérasọ, fọ́ọ̀mù ìgbaniṣíṣẹ́ ti dé! Ohun to ba ti ya kan, kii pẹ mọ, fọọmu igbaniṣiṣẹ fun ẹṣọ alaabo lawọn ipinlẹ Yoruba, Amọtẹkun yoo jade lọsẹ to n bọ. Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lo fọrọ yii lede lati ẹnu oludamọran rẹ lori ọrọ aabo, Alhaji Jimoh Dojumo. Gomina Akeredolu ṣalaye pe gbogbo eto lo ti to bayii lati gbe fọọmu naa sita. ''Awọn ọba alaye atawọn olori awujọ ni yoo ṣe oniduro fawọn eeyan wọn to ba fẹ darapọ mọ ẹṣọ alaabo Amọtẹkun,'' Akeredolu lo ṣalaye bẹẹ. Laipẹ yi ni awọn gomina guusu iwọ oorun ṣepade pẹlu igbakeji aarẹ, Yemi Oṣibajo ati agbẹjọro agba ni Naijiria, Abubakar Malami lati sọ asọyepọ lori eto naa. Malami ti kọkọ sọ pe, eto Amọtẹkun tawọn gomina ipinlẹ Yoruba gbe kale ko si ninu iwe ofin Naijiria. Ọpọ awọn ilumọọka agbẹjọro atawọn ajafẹtọ omoniyan lo ti ṣatilẹyin fun eto Amọtẹkun lẹyin ti tako agbekalẹ eto naa. Ọjọ kẹsan an oṣu kinni lawọn gomina ilẹ Yoruba ṣe agbekalẹ Amọtẹkun ni olu ilu ipinlẹ Oyo, Ibadan.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51410510
3politics
Edo State House of Assembly: Obaseki ní Oshiomole fẹ́ fipá gbàjọba lọ́wọ́ òun
Gẹgẹ bi ara igbesẹ ki ẹnikẹni ma joko ṣe ohunkohun ni ile aṣofin ipinlẹ Edo, gomina ipinlẹ naa, Godwin Obaseki ti paṣẹ ki wọn lọ yọ awọn orule ile naa igbimọ aṣofin naa lẹyin ti gomina ọhun atawọn agbofinro to fẹ fi tipa gbe ilẹkun ile nla naa ti pa ti gbe'na woju ara wọn. Ni kete to le awọn agbofinro naa jinna lo paṣẹ pe kawọn kọngila wa bẹrẹ atunṣe ileegbimọ naa. Gomina Ọbaseki ṣalaye fun BBC News latẹnu agbẹnusọ rẹ, Crusoe Osagie pe awọn alagbara oloṣelu kan pẹlu gomina ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria ni wọn gbimọ pọ lati fẹ fi tipa gba ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Edo ki wọn lee da rugudu silẹ ṣaaju idibo gomina to fẹ waye nibẹ lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹsan ọdun 2020. Gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Edo ṣe sọ, "Adams Oshiomhole atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kan, pẹlu gomina Hope Uzodinma lo wa nidi iṣẹlẹ naa. Wọn fẹ fi tipatipa gba akoso ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa eleyii ti wọn n tun ṣe lọwọlọwọ. A gbọ pe wọn lọ rọ ayederu ọpa aṣẹ ile naa eyi ti wọn fi fẹ ya bo ile igbimọ aṣofin ti ko si lẹnu iṣẹ bayii nitori atunṣe to n lọ lọwọ nibẹ, lati gbọna ti ko tọ ṣe agbekalẹ ileegbimọ aṣofin miran lowurọ Ọjọbọ. Gomina ipinlẹ Edo, olori ile aṣofin nibẹ, igbakeji olori ile aṣofin ipinlẹ naa wa ni ileegbimọ aṣofin naa lati ba igbesẹ naa jẹ. Fun oṣu meji bayii inu gbọngan ipade nla to wa ni ileegbimọ aṣofin naa lawọn ọmọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa ti n ṣe ipade wọn. Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Edo, ọgbẹni Crusoe Osagie fi ẹsun kan gomina ana ni ipinlẹ naa, Adams Oshiomhole to tun jẹ alaga ana fun ẹgbẹ oselu APC lo n gbiyanju lati fi ipa gba ile aṣofin naa. Ohun taa gbọ ni wi pe Gomina ipinlẹ Edo Godwin Obaseki ati igbakeji rẹ ti lọ tu awọn ọlọpaa to duro gbagba si ẹnu ọna ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Edo ti wọn si n gbiyanju ati fi tipa tikuuku wọle. Obitibiti ọlọpaa lo pejọpọ si Ile Igbimọ Aṣofin ipinlẹ Edo to wa ni ilu Benin. Awọn ọlọpaa naa yabo ile igbimọ aṣofin naa pẹlu ọkọ wọn, ti wọn si duro wamuwamu sibẹ. Eleyii n waye lẹyin wakati diẹ ti awọn aṣofin ipinlẹ naa yọ igbakeji abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa. Igbakeji Kọmisọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Edo, Ayoola Ajala lo dari awọn ọlọpaa naa. Ẹgbẹ oṣelu PDP loju opo Twitter ni ẹgbẹ oṣelu APC n lọ awọn ọlọpaa naa lati da ẹru ati ipaya silẹ ni ilu naa nitori Gomina Obaseki n gbajumọ si nipinlẹ naa. "Aug 2018 ni ìgbìmọ̀ aláṣẹ APC ti ṣe ìpàdé kẹ́yìn, Oshiomole ti kùnà" Àwọn gómìnà lábẹ́ àsía ẹgbẹ́ òṣẹ̀lú All Progressive Congress (APC) tí kési alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Adams Oshiomole lati pe ipade igbimọ alakoso ẹgbẹ́ tàbi kó kọ̀wé fipò sílẹ̀. Awọn gómìnà naa sàlàyé pé, bi alága apapọ ẹgbẹ kò se lee pe àwọn àgbàgbà ẹgbẹ́ sí ìpàdé, ti n mú idàrúdàpọ̀ bá ètò ẹgbẹ́. Oludari agba fun ẹgbẹ́ àwọn gomina, Salihu Lukman, lo kede bẹẹ nínú àtẹjáde kan to fọwọsí lọjọru nílùú Abuja. Àtẹjáde náà ni " kò sí ohunkohun miran, to ba ti yàto si ìpàdé ẹlẹgbẹ́jẹgbẹ́ tàbi ìpáde àpérò gbogboogbo, to lee parí ǹkan to ti dàrú nínú ètò ẹgbẹ́" "O sàn kí Oshiomhole bìkítà fún ilana ẹgbẹ́ to wa nínú iwe ofin ẹgbẹ́, láti pe ìpade àwọn èèkàn ẹgbẹ ki wọn lee sọ̀rọ̀ lórí gbogbo kùdìẹ̀kudiẹ̀ to n ba ẹgbẹ́ APC fínra, tàbi ko gba pé òun ko kunju òṣùwọ̀n láti tukọ ẹgbẹ̀, ko sì kọ̀wé fipò sílẹ̀." Lukman sàlàyé pé, o pọ̀ndandan ki Oshiomole kọwe fipo rẹ silẹ, paapaa pẹ̀lú ìròyìn to n jáde láti ìpínlẹ̀ Edo pé, àwọn oloye ẹgbẹ̀ APC ti díbò "a ò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀" fun Oshiomhole. "Dipo ka gbajumọ ọna ti APC yoo fi bori ninu awọn eto idibo to wa nilẹ, n se la n foju tẹnbẹlu ara wa. Gbogbo awọn ami buruku yii to waye ni ipinlẹ Zamfara, Rivers, Bauchi ati Adamawa lo tun fẹ suyọ abyi ni Bayelsa." Lukman fikun pe o se ni laanu pe igbimọ alakoso ẹgbẹ to yẹ ko wa ojutu sawọn isoro yii lo fẹ dabi eyi ti wọn ti so rọ. Osu kẹjọ ọdun 2018 ni wọn ti se ipade kẹyin, ti ẹka alasẹ to yẹ ko maa se amusẹ ipinnu ti igbimọ alakoso ba se, ti wa ja agbara gba mọ igbimọ alakoso ẹgbẹ lọwọ. Ẹgbẹ oṣelu APC ti bẹnu atẹ lu igbesẹ awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan ni ipinlẹ Edo, ti wọn lawọn paṣẹ lo fidimọle fun alaga ẹgbẹ naa lapapọ, Adams Oshiomole. Idahun yii n waye nitori bi ẹka ẹgbẹ naa nilu Benin ṣe ni oun ko ni igbagbọ mọ ninu alaga ẹgbẹ nipinlẹ ati alaga apapọ ẹgbẹ naa. Yakubu Nabena, to jẹ igbakeji akọwe ipolongo ẹgbẹ APC ṣalaye fun ikọ BBC pe, igbesẹ to yẹ kọ ni awọn to paṣẹ lọ gbele rẹ fun Oshiomole tẹle. O ni ''alawada lawọn to gbe iru igbesẹ yii'' nitori pe wọn ko laṣẹ lati paṣẹ lọ fidimọle fun alaga ẹgbẹ lapapọ. Ohun ti wọn ṣe ko mu ọgbọn wa rara. Wọn ni lati mọ nnkan ti ofin ẹgbẹ sọ ki wọn to gbe iru igbesẹ bẹẹ'' O wa ṣalaye pe, awọn igbesẹ kan wa labẹ ofin ẹgbẹ ti eeyan gbọdọ ṣe, ki o to le ni oun fẹ yọ alaga ẹgbẹ lapapọ ''Ni ipele nipele ni ohun gbogbo wa ninu eto. Ki eeyan to le yọ alaga ẹgbẹ lapapọ tabi ki wọn to le kọwe lọ joko sile fun-un, igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ lo le se bẹẹ.'' Ohun ta ti jabọ ṣaaju lori ọrọ yii Nkan ko ṣebi ẹni rọgbọ falaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress APC, Adams Oshiomole pẹlu bi awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan ni ipinlẹ Edo ṣe lawọn jawe lọ rọọkun nile fun un. Lọjọ Iṣẹgun niroyin gbori afẹfẹ kankan lẹyin ti ẹka ẹgbẹ naa ni Benin tii ṣe olu ilu Edo kede pe awọn jawe lọ rọọkun n'le falaga ẹgbẹ naa ni ipinlẹ ohuin, Anselm Ojezua. Ko pẹ si igba naa ni ikede miran wa lati ile ijọba pe wọn ti yọ akọwe ẹgbẹ naa ati pe wọn tun kọwe lọ fidimọlẹ fun alaga ẹgbẹ naa lapapọ Adams Oshiomole. Titi di bi a ti ṣe n ṣe akojọpọ iroyin yii, Adams Oshiomole tabi alaṣẹ ẹgbẹ naa kankan loke ko tii fesi si igbesẹ yi. Lẹnu ọjọ mẹta yii ni fa ki n fa ti n waye laarin Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ati Adams Oshiomole. Toun ti bi awọn agbagba ẹgbẹ naa ti ṣe gbiyanju lati dẹkun aigbọraẹniye laarin wọn,iṣẹlẹ to ṣẹlẹ yi n ṣafihan pe nnkan ko rọgbọ ni ipinlẹ naa falaga ẹgbẹ APC. Bi awọn kan ti ṣe ni awọn ko fẹ ri imi Oshiomole lakitan mọ lawọn agbarijọpọ alaga ijọba ibilẹ kan sọ pe gbọingbọin lawọn wa lẹyin rẹ. Gẹgẹ bi ohun ta ri ka ninu iwe iroyin Naijiria kan,atẹjade kan tawọn alaga Etsako West,Etsako Central fi sita sọ pe ''awa ni alaga ijọba ibilẹ mẹrindinlogun a o si mọ nipa ipade to waye nibi ti wọn ti kọwe akoniigbagbọ ninu rẹ mọ fun alaga ẹgbẹ wa Adams Oshiomole'' Wọn tẹsiwaju pe dipo Oshiomole,Gomina Godwin Obaseki lawọn ko ni igbagbọ ninu rẹ ati alaga ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Edo,Anselm Ojezua. Wọn wa tẹnumọ pe Oshiomole ṣi ni alaga olori awọn ati pe ''wamuwamu lawọn wa lẹyin rẹ''
Edo State House of Assembly: Obaseki ní Oshiomole fẹ́ fipá gbàjọba lọ́wọ́ òun Gẹgẹ bi ara igbesẹ ki ẹnikẹni ma joko ṣe ohunkohun ni ile aṣofin ipinlẹ Edo, gomina ipinlẹ naa, Godwin Obaseki ti paṣẹ ki wọn lọ yọ awọn orule ile naa igbimọ aṣofin naa lẹyin ti gomina ọhun atawọn agbofinro to fẹ fi tipa gbe ilẹkun ile nla naa ti pa ti gbe'na woju ara wọn. Ni kete to le awọn agbofinro naa jinna lo paṣẹ pe kawọn kọngila wa bẹrẹ atunṣe ileegbimọ naa. Gomina Ọbaseki ṣalaye fun BBC News latẹnu agbẹnusọ rẹ, Crusoe Osagie pe awọn alagbara oloṣelu kan pẹlu gomina ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria ni wọn gbimọ pọ lati fẹ fi tipa gba ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Edo ki wọn lee da rugudu silẹ ṣaaju idibo gomina to fẹ waye nibẹ lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹsan ọdun 2020. Gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Edo ṣe sọ, "Adams Oshiomhole atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kan, pẹlu gomina Hope Uzodinma lo wa nidi iṣẹlẹ naa. Wọn fẹ fi tipatipa gba akoso ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa eleyii ti wọn n tun ṣe lọwọlọwọ. A gbọ pe wọn lọ rọ ayederu ọpa aṣẹ ile naa eyi ti wọn fi fẹ ya bo ile igbimọ aṣofin ti ko si lẹnu iṣẹ bayii nitori atunṣe to n lọ lọwọ nibẹ, lati gbọna ti ko tọ ṣe agbekalẹ ileegbimọ aṣofin miran lowurọ Ọjọbọ. Gomina ipinlẹ Edo, olori ile aṣofin nibẹ, igbakeji olori ile aṣofin ipinlẹ naa wa ni ileegbimọ aṣofin naa lati ba igbesẹ naa jẹ. Fun oṣu meji bayii inu gbọngan ipade nla to wa ni ileegbimọ aṣofin naa lawọn ọmọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa ti n ṣe ipade wọn. Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Edo, ọgbẹni Crusoe Osagie fi ẹsun kan gomina ana ni ipinlẹ naa, Adams Oshiomhole to tun jẹ alaga ana fun ẹgbẹ oselu APC lo n gbiyanju lati fi ipa gba ile aṣofin naa. Ohun taa gbọ ni wi pe Gomina ipinlẹ Edo Godwin Obaseki ati igbakeji rẹ ti lọ tu awọn ọlọpaa to duro gbagba si ẹnu ọna ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Edo ti wọn si n gbiyanju ati fi tipa tikuuku wọle. Obitibiti ọlọpaa lo pejọpọ si Ile Igbimọ Aṣofin ipinlẹ Edo to wa ni ilu Benin. Awọn ọlọpaa naa yabo ile igbimọ aṣofin naa pẹlu ọkọ wọn, ti wọn si duro wamuwamu sibẹ. Eleyii n waye lẹyin wakati diẹ ti awọn aṣofin ipinlẹ naa yọ igbakeji abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa. Igbakeji Kọmisọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Edo, Ayoola Ajala lo dari awọn ọlọpaa naa. Ẹgbẹ oṣelu PDP loju opo Twitter ni ẹgbẹ oṣelu APC n lọ awọn ọlọpaa naa lati da ẹru ati ipaya silẹ ni ilu naa nitori Gomina Obaseki n gbajumọ si nipinlẹ naa. "Aug 2018 ni ìgbìmọ̀ aláṣẹ APC ti ṣe ìpàdé kẹ́yìn, Oshiomole ti kùnà" Àwọn gómìnà lábẹ́ àsía ẹgbẹ́ òṣẹ̀lú All Progressive Congress (APC) tí kési alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Adams Oshiomole lati pe ipade igbimọ alakoso ẹgbẹ́ tàbi kó kọ̀wé fipò sílẹ̀. Awọn gómìnà naa sàlàyé pé, bi alága apapọ ẹgbẹ kò se lee pe àwọn àgbàgbà ẹgbẹ́ sí ìpàdé, ti n mú idàrúdàpọ̀ bá ètò ẹgbẹ́. Oludari agba fun ẹgbẹ́ àwọn gomina, Salihu Lukman, lo kede bẹẹ nínú àtẹjáde kan to fọwọsí lọjọru nílùú Abuja. Àtẹjáde náà ni " kò sí ohunkohun miran, to ba ti yàto si ìpàdé ẹlẹgbẹ́jẹgbẹ́ tàbi ìpáde àpérò gbogboogbo, to lee parí ǹkan to ti dàrú nínú ètò ẹgbẹ́" "O sàn kí Oshiomhole bìkítà fún ilana ẹgbẹ́ to wa nínú iwe ofin ẹgbẹ́, láti pe ìpade àwọn èèkàn ẹgbẹ ki wọn lee sọ̀rọ̀ lórí gbogbo kùdìẹ̀kudiẹ̀ to n ba ẹgbẹ́ APC fínra, tàbi ko gba pé òun ko kunju òṣùwọ̀n láti tukọ ẹgbẹ̀, ko sì kọ̀wé fipò sílẹ̀." Lukman sàlàyé pé, o pọ̀ndandan ki Oshiomole kọwe fipo rẹ silẹ, paapaa pẹ̀lú ìròyìn to n jáde láti ìpínlẹ̀ Edo pé, àwọn oloye ẹgbẹ̀ APC ti díbò "a ò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀" fun Oshiomhole. "Dipo ka gbajumọ ọna ti APC yoo fi bori ninu awọn eto idibo to wa nilẹ, n se la n foju tẹnbẹlu ara wa. Gbogbo awọn ami buruku yii to waye ni ipinlẹ Zamfara, Rivers, Bauchi ati Adamawa lo tun fẹ suyọ abyi ni Bayelsa." Lukman fikun pe o se ni laanu pe igbimọ alakoso ẹgbẹ to yẹ ko wa ojutu sawọn isoro yii lo fẹ dabi eyi ti wọn ti so rọ. Osu kẹjọ ọdun 2018 ni wọn ti se ipade kẹyin, ti ẹka alasẹ to yẹ ko maa se amusẹ ipinnu ti igbimọ alakoso ba se, ti wa ja agbara gba mọ igbimọ alakoso ẹgbẹ lọwọ. Ẹgbẹ oṣelu APC ti bẹnu atẹ lu igbesẹ awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan ni ipinlẹ Edo, ti wọn lawọn paṣẹ lo fidimọle fun alaga ẹgbẹ naa lapapọ, Adams Oshiomole. Idahun yii n waye nitori bi ẹka ẹgbẹ naa nilu Benin ṣe ni oun ko ni igbagbọ mọ ninu alaga ẹgbẹ nipinlẹ ati alaga apapọ ẹgbẹ naa. Yakubu Nabena, to jẹ igbakeji akọwe ipolongo ẹgbẹ APC ṣalaye fun ikọ BBC pe, igbesẹ to yẹ kọ ni awọn to paṣẹ lọ gbele rẹ fun Oshiomole tẹle. O ni ''alawada lawọn to gbe iru igbesẹ yii'' nitori pe wọn ko laṣẹ lati paṣẹ lọ fidimọle fun alaga ẹgbẹ lapapọ. Ohun ti wọn ṣe ko mu ọgbọn wa rara. Wọn ni lati mọ nnkan ti ofin ẹgbẹ sọ ki wọn to gbe iru igbesẹ bẹẹ'' O wa ṣalaye pe, awọn igbesẹ kan wa labẹ ofin ẹgbẹ ti eeyan gbọdọ ṣe, ki o to le ni oun fẹ yọ alaga ẹgbẹ lapapọ ''Ni ipele nipele ni ohun gbogbo wa ninu eto. Ki eeyan to le yọ alaga ẹgbẹ lapapọ tabi ki wọn to le kọwe lọ joko sile fun-un, igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ lo le se bẹẹ.'' Ohun ta ti jabọ ṣaaju lori ọrọ yii Nkan ko ṣebi ẹni rọgbọ falaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress APC, Adams Oshiomole pẹlu bi awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan ni ipinlẹ Edo ṣe lawọn jawe lọ rọọkun nile fun un. Lọjọ Iṣẹgun niroyin gbori afẹfẹ kankan lẹyin ti ẹka ẹgbẹ naa ni Benin tii ṣe olu ilu Edo kede pe awọn jawe lọ rọọkun n'le falaga ẹgbẹ naa ni ipinlẹ ohuin, Anselm Ojezua. Ko pẹ si igba naa ni ikede miran wa lati ile ijọba pe wọn ti yọ akọwe ẹgbẹ naa ati pe wọn tun kọwe lọ fidimọlẹ fun alaga ẹgbẹ naa lapapọ Adams Oshiomole. Titi di bi a ti ṣe n ṣe akojọpọ iroyin yii, Adams Oshiomole tabi alaṣẹ ẹgbẹ naa kankan loke ko tii fesi si igbesẹ yi. Lẹnu ọjọ mẹta yii ni fa ki n fa ti n waye laarin Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ati Adams Oshiomole. Toun ti bi awọn agbagba ẹgbẹ naa ti ṣe gbiyanju lati dẹkun aigbọraẹniye laarin wọn,iṣẹlẹ to ṣẹlẹ yi n ṣafihan pe nnkan ko rọgbọ ni ipinlẹ naa falaga ẹgbẹ APC. Bi awọn kan ti ṣe ni awọn ko fẹ ri imi Oshiomole lakitan mọ lawọn agbarijọpọ alaga ijọba ibilẹ kan sọ pe gbọingbọin lawọn wa lẹyin rẹ. Gẹgẹ bi ohun ta ri ka ninu iwe iroyin Naijiria kan,atẹjade kan tawọn alaga Etsako West,Etsako Central fi sita sọ pe ''awa ni alaga ijọba ibilẹ mẹrindinlogun a o si mọ nipa ipade to waye nibi ti wọn ti kọwe akoniigbagbọ ninu rẹ mọ fun alaga ẹgbẹ wa Adams Oshiomole'' Wọn tẹsiwaju pe dipo Oshiomole,Gomina Godwin Obaseki lawọn ko ni igbagbọ ninu rẹ ati alaga ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Edo,Anselm Ojezua. Wọn wa tẹnumọ pe Oshiomole ṣi ni alaga olori awọn ati pe ''wamuwamu lawọn wa lẹyin rẹ''
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-50400798
2health
Coronavirus: Àjọ elétò ìlera lágbàyé tí pe Coronavirus ní àjàkálẹ̀ àrùn káàkiri àgbáyé
Ajọ eleto ilera ni Agbaye, WHO ti pe arun Coronavirus ni ajakalẹ arun to n ja kaakiri agbaye. Alaga ajọ WHO, Dokita Tedros Adhanom Ghebreyesus ni iye awọn eniyan to ti lugbadi awọn arun naa ni awọn orilẹede miran yatọ si China ti peleke si ni ida mẹtala laarin ọsẹ meji. Tedros Adhanom Ghebreyesus ni oun ṣe oun laanu pe awọn eniyan ko i tii kọ ibi ara si ajakalẹ arun naa . Ajakalẹ aarun tun mọ si pe arun naa n kaakiri orilẹede pupọ ni ẹẹkan naa. Amọ Tedros Adhanom Ghebreyesus ni pipe arun naa ni ajakalẹ aarun ko tu mọ si pe ko ni si ọna abayọ lati kapa aarun naa. Lati igba ti arun Coronavirus ti bẹ silẹ ni ilu Wuhan, lorilẹ-ede China lọdun 2019, ọpọloọpọ awọn eeyan lo ti lugbadi arun naa kaakiri agbaye. Bi arun naa ṣe n da ẹmi awọn eeyan legbodo na lo n fa idaduro si oriṣiriṣi awọn ayẹye, eto, ipade, ere idaraya atawọn nkan mii to yẹ ko waye. Iwọnyi ni awọn ohun to yẹ ko waye, ṣugbọn ti awọn ti ọrọ kan gbegile, tabi ṣe atunto rẹ nitori arun ọhun. Ọpọ ifẹṣewọnsẹ ere bọọlu ajọ Yuroopu, EPL, to yẹ ko waye ni wọn ti wọgile laipẹ yii, ti awọn alaboju ifẹsẹwọnsẹ naa pinnu pe ki diẹ lara ifẹsẹwọnsẹ naa waye lai si ero iworan. Fun apẹrẹ, wọn sun ifẹsẹwọnsẹ laarin ikọ Arsenal ati Manchester City to yẹ ko waye lọjọ kọkanla Oṣu Kẹta ọdun yii siwaju. Ni orillẹ-ede Italy, awọn alakoso ere bọọlu nibẹ, Italian Football Federation (FIGC) sọ lẹyin ipade kan pe, o ṣeṣe ki idije Serie A saa yii ma pari nitori arun naa. Ko tan sibẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu lagbaye, FIFA sọ pe, o ṣeṣe ko sun awọn igbaradi fun idije bọọlu agabye, Qatar 2022 siwaju. Ni ti idije Olimpiiki to yẹ ko bẹrẹ loṣu keje ọdun 2020, awọn igbimọ to n risi eto na ti ni kaka ki wọn wọgile, niṣe ni wọn yoo jẹ ko waye laisi ero iworan, ṣugbọn ko ṣeni to mọ ohun ti le ṣelẹ. Laarin ọsẹ yii ni ijọba Yuroopu wọgile gbogbo ohun to jẹ mọ ipade ita gbangba lati le dẹkun itankalẹ arun naa, koda, wọn gbẹsẹ le lilọ si ile ijọsin. Lọjọ Aje, ọjọ kẹsan an oṣu yii ni ijọba Ireland wọgile iwọde ayajọ ọjọ St. Patrick to waye ni Dublin. Ọpọ ibi ni Germany, paapaa ni Berlin ni wọn ti wọgile awọn ohun to le mu ki awọn eeyan korajọ pọ soju kan naa, bi ile iworan tiata, ati bẹbẹ lọ. Afihan ọkọ ayọkẹle ita gbangba to yẹ ko waye ni New York, lorilẹ-ede Amẹrika lọṣu Kẹrin ọdun 2020 naa ni wọn tun ti sun siwaju. Nilẹ Amẹrika, Sẹnatọ Bernie Sanders ati igbakeji aarẹ tẹlẹ, Jospeh Biden naa sun ipolongo idibo sipo aarẹ to yẹ ko waye lọjọ Kẹwa Oṣu Kẹta ọdun yii ni Ohio siwaju latari ibẹru arun Coronavirus. Ipade ajọ banki agabye ọlọdọdun to yẹ ko waye ni Washington ni wọn ti ṣatunto rẹ bayii. Awọn ti ọrọ kan ti wa wọrọko fi ṣada ni bi wọn ṣe gbe igbesẹ lati ṣe ipade naa lori itakun agbaye dipo ki wọn ṣe loju koju. Awọn ẹlesin Musulumi ti wọn ti n gbaradi lati goke Arafa lọdun yii ko le ni anfani ati ṣe bẹ nitori ọwọja arun Coronavirus yii kan naa. Laipẹ yii ni ijọba Saudi kede pe, wọn gbẹsẹle gbogbo irinajo okere si orilẹ-ede wọn fun igba diẹ titi ti arun ọhun yoo fi kasẹ nile. Fiimu James Bond kan ti awọn olotu rẹ lero pe yoo waye loṣu Kẹrin ọdun yii ni wọn ti sun siwaju. Sinima naa ti akọle rẹ n jẹ "No time to Die" ni wọn sun si Oṣu Kọkanla ọdun 2020 dipo Oṣu Kẹrin.
Coronavirus: Àjọ elétò ìlera lágbàyé tí pe Coronavirus ní àjàkálẹ̀ àrùn káàkiri àgbáyé Ajọ eleto ilera ni Agbaye, WHO ti pe arun Coronavirus ni ajakalẹ arun to n ja kaakiri agbaye. Alaga ajọ WHO, Dokita Tedros Adhanom Ghebreyesus ni iye awọn eniyan to ti lugbadi awọn arun naa ni awọn orilẹede miran yatọ si China ti peleke si ni ida mẹtala laarin ọsẹ meji. Tedros Adhanom Ghebreyesus ni oun ṣe oun laanu pe awọn eniyan ko i tii kọ ibi ara si ajakalẹ arun naa . Ajakalẹ aarun tun mọ si pe arun naa n kaakiri orilẹede pupọ ni ẹẹkan naa. Amọ Tedros Adhanom Ghebreyesus ni pipe arun naa ni ajakalẹ aarun ko tu mọ si pe ko ni si ọna abayọ lati kapa aarun naa. Lati igba ti arun Coronavirus ti bẹ silẹ ni ilu Wuhan, lorilẹ-ede China lọdun 2019, ọpọloọpọ awọn eeyan lo ti lugbadi arun naa kaakiri agbaye. Bi arun naa ṣe n da ẹmi awọn eeyan legbodo na lo n fa idaduro si oriṣiriṣi awọn ayẹye, eto, ipade, ere idaraya atawọn nkan mii to yẹ ko waye. Iwọnyi ni awọn ohun to yẹ ko waye, ṣugbọn ti awọn ti ọrọ kan gbegile, tabi ṣe atunto rẹ nitori arun ọhun. Ọpọ ifẹṣewọnsẹ ere bọọlu ajọ Yuroopu, EPL, to yẹ ko waye ni wọn ti wọgile laipẹ yii, ti awọn alaboju ifẹsẹwọnsẹ naa pinnu pe ki diẹ lara ifẹsẹwọnsẹ naa waye lai si ero iworan. Fun apẹrẹ, wọn sun ifẹsẹwọnsẹ laarin ikọ Arsenal ati Manchester City to yẹ ko waye lọjọ kọkanla Oṣu Kẹta ọdun yii siwaju. Ni orillẹ-ede Italy, awọn alakoso ere bọọlu nibẹ, Italian Football Federation (FIGC) sọ lẹyin ipade kan pe, o ṣeṣe ki idije Serie A saa yii ma pari nitori arun naa. Ko tan sibẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu lagbaye, FIFA sọ pe, o ṣeṣe ko sun awọn igbaradi fun idije bọọlu agabye, Qatar 2022 siwaju. Ni ti idije Olimpiiki to yẹ ko bẹrẹ loṣu keje ọdun 2020, awọn igbimọ to n risi eto na ti ni kaka ki wọn wọgile, niṣe ni wọn yoo jẹ ko waye laisi ero iworan, ṣugbọn ko ṣeni to mọ ohun ti le ṣelẹ. Laarin ọsẹ yii ni ijọba Yuroopu wọgile gbogbo ohun to jẹ mọ ipade ita gbangba lati le dẹkun itankalẹ arun naa, koda, wọn gbẹsẹ le lilọ si ile ijọsin. Lọjọ Aje, ọjọ kẹsan an oṣu yii ni ijọba Ireland wọgile iwọde ayajọ ọjọ St. Patrick to waye ni Dublin. Ọpọ ibi ni Germany, paapaa ni Berlin ni wọn ti wọgile awọn ohun to le mu ki awọn eeyan korajọ pọ soju kan naa, bi ile iworan tiata, ati bẹbẹ lọ. Afihan ọkọ ayọkẹle ita gbangba to yẹ ko waye ni New York, lorilẹ-ede Amẹrika lọṣu Kẹrin ọdun 2020 naa ni wọn tun ti sun siwaju. Nilẹ Amẹrika, Sẹnatọ Bernie Sanders ati igbakeji aarẹ tẹlẹ, Jospeh Biden naa sun ipolongo idibo sipo aarẹ to yẹ ko waye lọjọ Kẹwa Oṣu Kẹta ọdun yii ni Ohio siwaju latari ibẹru arun Coronavirus. Ipade ajọ banki agabye ọlọdọdun to yẹ ko waye ni Washington ni wọn ti ṣatunto rẹ bayii. Awọn ti ọrọ kan ti wa wọrọko fi ṣada ni bi wọn ṣe gbe igbesẹ lati ṣe ipade naa lori itakun agbaye dipo ki wọn ṣe loju koju. Awọn ẹlesin Musulumi ti wọn ti n gbaradi lati goke Arafa lọdun yii ko le ni anfani ati ṣe bẹ nitori ọwọja arun Coronavirus yii kan naa. Laipẹ yii ni ijọba Saudi kede pe, wọn gbẹsẹle gbogbo irinajo okere si orilẹ-ede wọn fun igba diẹ titi ti arun ọhun yoo fi kasẹ nile. Fiimu James Bond kan ti awọn olotu rẹ lero pe yoo waye loṣu Kẹrin ọdun yii ni wọn ti sun siwaju. Sinima naa ti akọle rẹ n jẹ "No time to Die" ni wọn sun si Oṣu Kọkanla ọdun 2020 dipo Oṣu Kẹrin.
https://www.bbc.com/yoruba/agbaye-51830526
3politics
Ekiti Governorship Election: Gómìnà Fayemi ní kí òṣìṣẹ́ tó bá fẹ́ du ipò gómìnà fi ipò sílẹ̀
Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ti paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ni ijọba rẹ lati fi ipo silẹ ti wọn ba fẹ du ipo gomina ni ipinlẹ Ekiti. Ninu atẹjade gba ọwọ agbẹnusọ fun gomina Fayemi, Yinka Oyebode ni wọn ti fi lede pe Ọjọ Kẹrinla, Osu Kejila ni gomina fun wọn da lati fi ipo silẹ ni ijọba oun. Oyebode ni gomina gbe igbesẹ naa lọna ati rii pe awọn oṣiṣẹ to wa ni ijọba oun ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ lai si magomago. Bakan naa ni wọn fi kun un pe eyi tẹlẹ aṣẹ eto idibo lorilẹede Naijiria, paapaa saaju idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Ekiti. ''Lọna ati tẹle aṣẹ Ajọ INEC ati ẹgbẹ oṣelu APC ti yoo bẹrẹ idibo abẹle ni Oṣu Kini ọdun 2022, ti idibo sipo gomina naa yoo si waye ni Osu Kẹfa, ọdun 2022 kan naa.'' Lara awọn to wa ni ijọba gomina Fayemi ti awọn eniyan lero wi pe wọn fẹ fu ipo yii ni Akọwe ijọba, Biodun Oyebanji, Adari oṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti, Biodun Ọmọlẹyẹ, kọmiṣọnna fun ọrọ awujọ, Bamidele Faparusi ati oluranlọwọ pataki si gomina, Ọjọgbọn Bolaji Aluko laarin awọn miran.
Ekiti Governorship Election: Gómìnà Fayemi ní kí òṣìṣẹ́ tó bá fẹ́ du ipò gómìnà fi ipò sílẹ̀ Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ti paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ni ijọba rẹ lati fi ipo silẹ ti wọn ba fẹ du ipo gomina ni ipinlẹ Ekiti. Ninu atẹjade gba ọwọ agbẹnusọ fun gomina Fayemi, Yinka Oyebode ni wọn ti fi lede pe Ọjọ Kẹrinla, Osu Kejila ni gomina fun wọn da lati fi ipo silẹ ni ijọba oun. Oyebode ni gomina gbe igbesẹ naa lọna ati rii pe awọn oṣiṣẹ to wa ni ijọba oun ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ lai si magomago. Bakan naa ni wọn fi kun un pe eyi tẹlẹ aṣẹ eto idibo lorilẹede Naijiria, paapaa saaju idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Ekiti. ''Lọna ati tẹle aṣẹ Ajọ INEC ati ẹgbẹ oṣelu APC ti yoo bẹrẹ idibo abẹle ni Oṣu Kini ọdun 2022, ti idibo sipo gomina naa yoo si waye ni Osu Kẹfa, ọdun 2022 kan naa.'' Lara awọn to wa ni ijọba gomina Fayemi ti awọn eniyan lero wi pe wọn fẹ fu ipo yii ni Akọwe ijọba, Biodun Oyebanji, Adari oṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti, Biodun Ọmọlẹyẹ, kọmiṣọnna fun ọrọ awujọ, Bamidele Faparusi ati oluranlọwọ pataki si gomina, Ọjọgbọn Bolaji Aluko laarin awọn miran.
https://www.bbc.com/yoruba/media-59501292
1entertainment
World theatre Day: Kosoko ní ètò adójútòfò wà fọ́jọ́ alẹ́ àwọn onítíátà
Agba ọjẹ kan nidi isẹ tiata, to jẹ odu, ti kii se aimọ fun oloko laarin awọn osere tiata, Ọmọọba Jide Kosọkọ ni ẹgbẹ awọn osere ori itage lede Yoruba, taa mọ si TAMPAN, ti n se gudugudu meje, ati yaya mẹfa fun eto adojutodo fawọn ọmọ ẹgbẹ naa. Kosoko ni amọ irufẹ eto adojutofo yii ko ba ti waye tipẹ fawọn osere tiata Yoruba, bi kii ba se ọpọ wọn to pagi dina eto naa nigba naa, apẹyinda iwa aidaa yii si ni ọpọ wọn to n saisan n jẹ loni yii. Jide Kosoko wa tun rọ awọn ọmọ ẹgbẹ osere tiata lede Yoruba lati maa tọju ara wọn, ki wọn ma si lo gbogbo owo ti wọn n ri lati fi jẹnu tan, amọ ki wọn pọn omi silẹ de oungbẹ fun ọjọ alẹ.
World theatre Day: Kosoko ní ètò adójútòfò wà fọ́jọ́ alẹ́ àwọn onítíátà Agba ọjẹ kan nidi isẹ tiata, to jẹ odu, ti kii se aimọ fun oloko laarin awọn osere tiata, Ọmọọba Jide Kosọkọ ni ẹgbẹ awọn osere ori itage lede Yoruba, taa mọ si TAMPAN, ti n se gudugudu meje, ati yaya mẹfa fun eto adojutodo fawọn ọmọ ẹgbẹ naa. Kosoko ni amọ irufẹ eto adojutofo yii ko ba ti waye tipẹ fawọn osere tiata Yoruba, bi kii ba se ọpọ wọn to pagi dina eto naa nigba naa, apẹyinda iwa aidaa yii si ni ọpọ wọn to n saisan n jẹ loni yii. Jide Kosoko wa tun rọ awọn ọmọ ẹgbẹ osere tiata lede Yoruba lati maa tọju ara wọn, ki wọn ma si lo gbogbo owo ti wọn n ri lati fi jẹnu tan, amọ ki wọn pọn omi silẹ de oungbẹ fun ọjọ alẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-47716370
1entertainment
Goriola Hassan: ‘Tattoo’ tó wà lára mi, kò dí ọba jíjẹ lọ́wọ́, ara oge ṣíṣe ni
Gẹgẹ bi aṣa ilẹ Yoruba, o ni awọn etutu kan ti ilu gbọdọ ṣe ati eyi ti ọmọ oye to ba fẹ jọba naa ni lati ṣe, ki o to le gori oye. Amọ, o dabi ẹni pe gbogbo nkan lo ti yipada bayii bo ya nitori pe aye ti di aye ọlaju ni. Oṣere tiata kan ree, Goriola Hassan to sọ pe, oun ko ṣe etutu kankan, ki oun to jẹ ọba ilẹ Uba Imobi nilẹ Ijẹbu nipinlẹ Ogun. Ọgbẹni Hassan to ti jẹ Ọba ilẹ Uba Imobi bayii sọ pe, lootọọ ni pe wọn gbọdọ ṣe awọn eto, amọ ni toun, ko si ohun to jọ etutu rara. ''Ko digba ti wọn ba to lo odidi eeyan ṣe irubọ, ki eeyan to le jọba, a o ni lati faye ni ẹnikeji lara,'' Oba ilẹ Uba lo sọ bẹẹ. Bakan naa ni Kabiyesi Uba ṣalaye pe, oye ti oun jẹ ko na oun owo bii ti wulẹ ko mọ. Oba ilẹ Uba ni ''idile ọba ni wọn bi mi si, ati idile mama ati baba mi ni wọn n maa n jọba.'' O nigba ti oun de lati orilẹede Amerika, lawọn araalu wa ba oun pe ki oun jẹ ọba ilẹ Uba. ''Mi o ni lati nawo kankan, awọn ilu gan an lo ṣe inawo ibẹ,'' Kabiyesi Uba lo ṣalaye bẹẹ. Lori ọrọ awọn olori laafin, Oba ilẹ Uba ni oju kan lada ni lọrọ oun, o ni iyawo kan toun ni, ti tẹ oun lọrun. ''Mi o le nifẹ obinrin meji pọ lẹẹkan naa, nitori naa, o maa nira fun mi lati ni olori meji laafin,'' Oba Uba lo woye bẹẹ. Bẹẹ ba si gbagbe, gbajumọ osere tẹlẹ naa lo fẹ ọkan lara awọn osere tiata lobinrin, Ayo Adesanya, ko to di pe aarin wọn daru. Kabiyesi tun sọ fawọn akọroyin pe, ko si ohun tuntun labẹ ọrun mọ lori laali tawọn oloyinbo n pe ni ''tattoos'' to wa lara oun. O ni lati ayebaye lawọn Yoruba ti maa n le laali sara fun oge ṣiṣe, ''laye ode oni ni wọn kan n pe ni ''tattoo.'' Lakotan, Kabiyesi Uba ni oun n gbero lati pe awọn gbajugbaja oṣere tiata wa si ilẹ Uba, lati le wa dokoowo ki awọn araalu si jẹ anfaani rẹ.
Goriola Hassan: ‘Tattoo’ tó wà lára mi, kò dí ọba jíjẹ lọ́wọ́, ara oge ṣíṣe ni Gẹgẹ bi aṣa ilẹ Yoruba, o ni awọn etutu kan ti ilu gbọdọ ṣe ati eyi ti ọmọ oye to ba fẹ jọba naa ni lati ṣe, ki o to le gori oye. Amọ, o dabi ẹni pe gbogbo nkan lo ti yipada bayii bo ya nitori pe aye ti di aye ọlaju ni. Oṣere tiata kan ree, Goriola Hassan to sọ pe, oun ko ṣe etutu kankan, ki oun to jẹ ọba ilẹ Uba Imobi nilẹ Ijẹbu nipinlẹ Ogun. Ọgbẹni Hassan to ti jẹ Ọba ilẹ Uba Imobi bayii sọ pe, lootọọ ni pe wọn gbọdọ ṣe awọn eto, amọ ni toun, ko si ohun to jọ etutu rara. ''Ko digba ti wọn ba to lo odidi eeyan ṣe irubọ, ki eeyan to le jọba, a o ni lati faye ni ẹnikeji lara,'' Oba ilẹ Uba lo sọ bẹẹ. Bakan naa ni Kabiyesi Uba ṣalaye pe, oye ti oun jẹ ko na oun owo bii ti wulẹ ko mọ. Oba ilẹ Uba ni ''idile ọba ni wọn bi mi si, ati idile mama ati baba mi ni wọn n maa n jọba.'' O nigba ti oun de lati orilẹede Amerika, lawọn araalu wa ba oun pe ki oun jẹ ọba ilẹ Uba. ''Mi o ni lati nawo kankan, awọn ilu gan an lo ṣe inawo ibẹ,'' Kabiyesi Uba lo ṣalaye bẹẹ. Lori ọrọ awọn olori laafin, Oba ilẹ Uba ni oju kan lada ni lọrọ oun, o ni iyawo kan toun ni, ti tẹ oun lọrun. ''Mi o le nifẹ obinrin meji pọ lẹẹkan naa, nitori naa, o maa nira fun mi lati ni olori meji laafin,'' Oba Uba lo woye bẹẹ. Bẹẹ ba si gbagbe, gbajumọ osere tẹlẹ naa lo fẹ ọkan lara awọn osere tiata lobinrin, Ayo Adesanya, ko to di pe aarin wọn daru. Kabiyesi tun sọ fawọn akọroyin pe, ko si ohun tuntun labẹ ọrun mọ lori laali tawọn oloyinbo n pe ni ''tattoos'' to wa lara oun. O ni lati ayebaye lawọn Yoruba ti maa n le laali sara fun oge ṣiṣe, ''laye ode oni ni wọn kan n pe ni ''tattoo.'' Lakotan, Kabiyesi Uba ni oun n gbero lati pe awọn gbajugbaja oṣere tiata wa si ilẹ Uba, lati le wa dokoowo ki awọn araalu si jẹ anfaani rẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-55686576
3politics
Anti-Open Grazing law: Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo buwọ́lu òfín máfi ẹran jẹko láàrín ìgboro
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti buwọlu ofin mafi ẹran jẹko nigboro nipinlẹ naa. Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ọsẹ diẹ ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ọhun buwọlu abadofin naa. Eyii to n tumọ si pe ipinlẹ Ondo ti di ọkan lara awọn ipinlẹ ni iha guusu Naijiria to gbe ofin kalẹ tako fifi ẹran jẹ oko tabi da maalu laarin ilu. Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna eto iroyin ni ipinlẹ Ondo, Donald Ojogo Buwọlu, o ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjo, ọdun 2021, ni Akaredolu buwọlu ofin naa. Atẹjade ọhun ni "Ofin yii wa ni ilana adehun ti awọn gomina iha guusu Naijiria fẹnuko le lori nibi ipade ti wọn ṣe kẹyin nipinlẹ Eko, nibi ti wọn ti da ọjọ kinin, oṣu Kẹsan an, ọdun 2021 lati buwọlu ofin tuntun yii." "Ofin yii jẹ ọna kan lati pana rogbodiyan to maa n waye larin awọn eeyan kan atawọn eeyan ipinlẹ Ondo." Atẹjade naa tẹsiwaju pe ofin tuntun naa yoo tubọ mu ki irẹpọ to peye wa laarin awọn olugbe ipinlẹ Ondo, lai wo ti ẹya tabi ẹsin wọn. Kọmiṣọna naa tẹsiwaju pe ijọba ipinlẹ Ondo yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ lati ri daju pe awọn eeyan tẹle ofin tuntun naa. O ni "Ijọba yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ lati labẹ ofin lati ri pe ẹnikẹni ko tapa si ofin naa." O pari ọrọ rẹ pe ijọba yoo tẹ ofin ọhun sita ki awọn araalu le ni anfaani lati kaa, to fi mọ awọn ohun miran to tọ ki wọn mọ nipa ofin tuntun naa.
Anti-Open Grazing law: Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo buwọ́lu òfín máfi ẹran jẹko láàrín ìgboro Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti buwọlu ofin mafi ẹran jẹko nigboro nipinlẹ naa. Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ọsẹ diẹ ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ọhun buwọlu abadofin naa. Eyii to n tumọ si pe ipinlẹ Ondo ti di ọkan lara awọn ipinlẹ ni iha guusu Naijiria to gbe ofin kalẹ tako fifi ẹran jẹ oko tabi da maalu laarin ilu. Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna eto iroyin ni ipinlẹ Ondo, Donald Ojogo Buwọlu, o ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjo, ọdun 2021, ni Akaredolu buwọlu ofin naa. Atẹjade ọhun ni "Ofin yii wa ni ilana adehun ti awọn gomina iha guusu Naijiria fẹnuko le lori nibi ipade ti wọn ṣe kẹyin nipinlẹ Eko, nibi ti wọn ti da ọjọ kinin, oṣu Kẹsan an, ọdun 2021 lati buwọlu ofin tuntun yii." "Ofin yii jẹ ọna kan lati pana rogbodiyan to maa n waye larin awọn eeyan kan atawọn eeyan ipinlẹ Ondo." Atẹjade naa tẹsiwaju pe ofin tuntun naa yoo tubọ mu ki irẹpọ to peye wa laarin awọn olugbe ipinlẹ Ondo, lai wo ti ẹya tabi ẹsin wọn. Kọmiṣọna naa tẹsiwaju pe ijọba ipinlẹ Ondo yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ lati ri daju pe awọn eeyan tẹle ofin tuntun naa. O ni "Ijọba yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ lati labẹ ofin lati ri pe ẹnikẹni ko tapa si ofin naa." O pari ọrọ rẹ pe ijọba yoo tẹ ofin ọhun sita ki awọn araalu le ni anfaani lati kaa, to fi mọ awọn ohun miran to tọ ki wọn mọ nipa ofin tuntun naa.
https://www.bbc.com/yoruba/58398583
4religion
Social media abuse: Oyedepo ní àlòjù Twitter, Facebook àti Instagram máa ń ṣàkóbá fún àyànmọ́ ẹ̀dá
Oludari agba fasiti Covenant to wa niluu Ota, nipinlẹ Ogun, Ọmọwe David Oyedepo ti gbawọn ọdọ ni imọran lati ye wa lori ẹrọ ayelujara ni gbogbo igba. Biṣọọbu ijọ Living Faith ti ọpọ mọ si Winners Chapel sọrọ yii nibi ayẹyẹ ikẹkọọ jade fasiti Covenant ẹlẹẹkẹẹdogun rẹ lọjọ Ẹti. Oludasilẹ ijọ Winners Chapel ni aloju oju opo ayelujara maa n ṣakoba nla fawọn ọdọ. O ni lilo oju opo ayelujara lọna aitọ kii jẹ k'awọn ọdọ le kọju mọ ohun ti wọn n ṣe eyi ti yoo pada ṣakoba fún ọjọ ọla wọn. "Wiwa loju opo ayelujara ni gbogbo igba ti gba akoko lati ronu, awọn mii le ba ọrẹ wọn sọrọ lori ayelujara lati aarọ di alẹ. Awọn onimọ kan tiẹ sọ pe isọri kan naa ni aloju oju opo ayelujara ati mimu oogun oloro, ọti ati ṣiṣe ṣina jọ wa," Oyedepo ṣalaye. Biṣọọbu Oyedepo ni wiwa loju opo ayelujara ni gbogbo igba ti gba aye tawọn ọdọ fi le ṣe nkan iyebiye lọwọ wọn. Pasitọ ijọ Winners sọ pe igbe aye ti ko ba ni afojusun kan gbogii ko ni ìtumọ kankan. O ni awọn ti wọn ba ni afojusun ibi ti wọn ba n lọ nikan lo le dé ebute ayọ ayanmọ wọn. Oyedepo ni asiko ti to fawọn ọdọ lati ji giri ki wọn sì ṣiṣẹ lori ọjọ.
Social media abuse: Oyedepo ní àlòjù Twitter, Facebook àti Instagram máa ń ṣàkóbá fún àyànmọ́ ẹ̀dá Oludari agba fasiti Covenant to wa niluu Ota, nipinlẹ Ogun, Ọmọwe David Oyedepo ti gbawọn ọdọ ni imọran lati ye wa lori ẹrọ ayelujara ni gbogbo igba. Biṣọọbu ijọ Living Faith ti ọpọ mọ si Winners Chapel sọrọ yii nibi ayẹyẹ ikẹkọọ jade fasiti Covenant ẹlẹẹkẹẹdogun rẹ lọjọ Ẹti. Oludasilẹ ijọ Winners Chapel ni aloju oju opo ayelujara maa n ṣakoba nla fawọn ọdọ. O ni lilo oju opo ayelujara lọna aitọ kii jẹ k'awọn ọdọ le kọju mọ ohun ti wọn n ṣe eyi ti yoo pada ṣakoba fún ọjọ ọla wọn. "Wiwa loju opo ayelujara ni gbogbo igba ti gba akoko lati ronu, awọn mii le ba ọrẹ wọn sọrọ lori ayelujara lati aarọ di alẹ. Awọn onimọ kan tiẹ sọ pe isọri kan naa ni aloju oju opo ayelujara ati mimu oogun oloro, ọti ati ṣiṣe ṣina jọ wa," Oyedepo ṣalaye. Biṣọọbu Oyedepo ni wiwa loju opo ayelujara ni gbogbo igba ti gba aye tawọn ọdọ fi le ṣe nkan iyebiye lọwọ wọn. Pasitọ ijọ Winners sọ pe igbe aye ti ko ba ni afojusun kan gbogii ko ni ìtumọ kankan. O ni awọn ti wọn ba ni afojusun ibi ti wọn ba n lọ nikan lo le dé ebute ayọ ayanmọ wọn. Oyedepo ni asiko ti to fawọn ọdọ lati ji giri ki wọn sì ṣiṣẹ lori ọjọ.
https://www.bbc.com/yoruba/57206109
2health
Penis in Padlock: Ọkùnrin tó fi nǹkan ọkùnrin rẹ̀ sínú àgádágodo torí adùn ìbálòpọ̀ wọ gàù
Ọrọ buruku t'ohun ti ẹrin. Boya ẹfun ni, tabi eedi ni ka pe, a ko ti ẹ mọ orin ti eeyan i ba kọ si iṣẹlẹ kan to ṣẹlẹ si arakunrin kan. Niṣe ni ọkunrin naa fi ọwọ ara rẹ se ara rẹ pa, lẹyin ti nkan ọmọkunrin rẹ há sinu agadagodo 'padlock' fun ọsẹ meji gbako. Ẹyin naa sọ pe ha! Ọrọ to gbẹnu tan, to ya ni lẹnu silẹ dẹẹrẹ-dẹẹrẹ ni ọrọ ọkunrin naa. Iroyin sọ pe niṣe ni arakunrin yii, ki nkan ọmọkunrin rẹ sinu iho agadagodo kan. Iya ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogoji naa, sọ fun awọn akọroyin pe ọmọ oun fẹran lati ma a ki nkan ọmọkunrin rẹ si inu iho kekeeke. Ọkunrin naa to jẹ àpọn, to si n gbe ni orilẹ-ede Thailand ni iroyin sọ pe, o fi agadagodo onirin naa yii ọrun nnkan ọmọkunrin rẹ ka, lati ni adun ibalopọ, to si ti i pa. Amọ ọrọ bẹyin yọ fun nigba to fẹ ẹ ṣi, ṣugbọn ti kọkọrọ agadagodo naa ti sọnu. O gbiyanju titi lati yọ agadagodo kekere naa, ṣugbọn òfo ni igbiyanju rẹ ja si. Lo ba fi silẹ sibẹ fun ọsẹ meji o le. Kato o wi, ka to o fọ, kokoro aifojuri wọ inu nnkan ọmọkunrin rẹ, ni irora ba bẹrẹ ninu agọ ara rẹ, eyi to mu ko sare lọ sileewosan kan nilu Bangkok. Iya arakunrin naa ṣalaye fun awọn oṣisẹ eto ilera ṣe itọju rẹ nile pe "ko ni ọrẹbinrin to jẹ ololufẹ rẹ". "Airikan ṣe kan lo mu ko ṣe nkan to sẹ, nitori pe kii fi bẹẹ jade mọ nitori itankalẹ Covid-19. "O sọ fun mi pe oun ṣe nkan naa nitori pe oun ko ri nkan ṣe, ati pe oun fẹran lati ma a ki nkan ọmọkunrin oun si inu iho kekeeke. "Mo binu si fun bo ṣe fi mi ṣe ẹlẹya yii, mo si ti sọ fun pe ko ma ṣe iru rẹ mọ." Pẹlu iṣẹ abẹ si ni awọn dokita fi ge agadagodo naa kuro lara nkan ọmọkunrin rẹ, ti ipalara to ti mu ba a si lagbara ju nkan ti awọn dokita lero lọ. Eyi gan-an lo fa a ti wọn fi sare gbe digba-digba lọ sileewosan. Wọn lo ju ọgbọn iṣẹju lọ lati fi irinṣẹ to n lo ina ijọba lati fi ge agadagodo naa. Koda, wọn ni lati fi irin pelebe kan si aarin irin agadagodo ati ẹran ara ọkunrin yii, ko ma ba a ni ifarapa. Bakan naa ni wọn n fi omi wọn ara rẹ yika ibi ti agadagodo wa. Ẹnikan lara awọn to doola rẹ, Thongchai Donson sọ pe niṣe lo n pariwo nileewosan, nitori irora to ni. O ni awọn fi orukọ bo ọkunrin naa laṣiri, ṣugbọn ki awọn eeyan fi ọrọ rẹ kọgbọn. Botilẹ jẹ pe o ti gba ominira kuro ninu ide afọwọfa, awọn eleto ilera sọ pe o sẹ e ṣe ki akoba ayeraye ti wa lara rẹ, nitori iye asiko ti agadagodo naa lo nibẹ. Wọn tun sọ pe nkan ọmọkunrin naa ko ri boṣeyẹ ko ri mọ.
Penis in Padlock: Ọkùnrin tó fi nǹkan ọkùnrin rẹ̀ sínú àgádágodo torí adùn ìbálòpọ̀ wọ gàù Ọrọ buruku t'ohun ti ẹrin. Boya ẹfun ni, tabi eedi ni ka pe, a ko ti ẹ mọ orin ti eeyan i ba kọ si iṣẹlẹ kan to ṣẹlẹ si arakunrin kan. Niṣe ni ọkunrin naa fi ọwọ ara rẹ se ara rẹ pa, lẹyin ti nkan ọmọkunrin rẹ há sinu agadagodo 'padlock' fun ọsẹ meji gbako. Ẹyin naa sọ pe ha! Ọrọ to gbẹnu tan, to ya ni lẹnu silẹ dẹẹrẹ-dẹẹrẹ ni ọrọ ọkunrin naa. Iroyin sọ pe niṣe ni arakunrin yii, ki nkan ọmọkunrin rẹ sinu iho agadagodo kan. Iya ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogoji naa, sọ fun awọn akọroyin pe ọmọ oun fẹran lati ma a ki nkan ọmọkunrin rẹ si inu iho kekeeke. Ọkunrin naa to jẹ àpọn, to si n gbe ni orilẹ-ede Thailand ni iroyin sọ pe, o fi agadagodo onirin naa yii ọrun nnkan ọmọkunrin rẹ ka, lati ni adun ibalopọ, to si ti i pa. Amọ ọrọ bẹyin yọ fun nigba to fẹ ẹ ṣi, ṣugbọn ti kọkọrọ agadagodo naa ti sọnu. O gbiyanju titi lati yọ agadagodo kekere naa, ṣugbọn òfo ni igbiyanju rẹ ja si. Lo ba fi silẹ sibẹ fun ọsẹ meji o le. Kato o wi, ka to o fọ, kokoro aifojuri wọ inu nnkan ọmọkunrin rẹ, ni irora ba bẹrẹ ninu agọ ara rẹ, eyi to mu ko sare lọ sileewosan kan nilu Bangkok. Iya arakunrin naa ṣalaye fun awọn oṣisẹ eto ilera ṣe itọju rẹ nile pe "ko ni ọrẹbinrin to jẹ ololufẹ rẹ". "Airikan ṣe kan lo mu ko ṣe nkan to sẹ, nitori pe kii fi bẹẹ jade mọ nitori itankalẹ Covid-19. "O sọ fun mi pe oun ṣe nkan naa nitori pe oun ko ri nkan ṣe, ati pe oun fẹran lati ma a ki nkan ọmọkunrin oun si inu iho kekeeke. "Mo binu si fun bo ṣe fi mi ṣe ẹlẹya yii, mo si ti sọ fun pe ko ma ṣe iru rẹ mọ." Pẹlu iṣẹ abẹ si ni awọn dokita fi ge agadagodo naa kuro lara nkan ọmọkunrin rẹ, ti ipalara to ti mu ba a si lagbara ju nkan ti awọn dokita lero lọ. Eyi gan-an lo fa a ti wọn fi sare gbe digba-digba lọ sileewosan. Wọn lo ju ọgbọn iṣẹju lọ lati fi irinṣẹ to n lo ina ijọba lati fi ge agadagodo naa. Koda, wọn ni lati fi irin pelebe kan si aarin irin agadagodo ati ẹran ara ọkunrin yii, ko ma ba a ni ifarapa. Bakan naa ni wọn n fi omi wọn ara rẹ yika ibi ti agadagodo wa. Ẹnikan lara awọn to doola rẹ, Thongchai Donson sọ pe niṣe lo n pariwo nileewosan, nitori irora to ni. O ni awọn fi orukọ bo ọkunrin naa laṣiri, ṣugbọn ki awọn eeyan fi ọrọ rẹ kọgbọn. Botilẹ jẹ pe o ti gba ominira kuro ninu ide afọwọfa, awọn eleto ilera sọ pe o sẹ e ṣe ki akoba ayeraye ti wa lara rẹ, nitori iye asiko ti agadagodo naa lo nibẹ. Wọn tun sọ pe nkan ọmọkunrin naa ko ri boṣeyẹ ko ri mọ.
https://www.bbc.com/yoruba/agbaye-57879059
3politics
2023 elections: Afenifere ní ipò Ààrẹ gbọdọ̀ padà sí ẹkùn gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà lọ́dún tó ń bọ̀
Ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀ Yorùbá ti lùlù àtìlẹyìn fún ẹgbẹ́ àwọn gómìnà gúúsù ilẹ̀ gúúsù Nàìjíríà (SGF) lórí pé ipò Ààrẹ gbọdọ̀ wá láti ẹkùn Gúúsù orílẹ̀ èdè yìí lọ́dún 2023. Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹjọ, oṣù kejì ni Gómìnà Rotimi Akeredolu ti ìpínlẹ̀ Ondo tó jẹ́ alága SGF sọ fún àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìṣípò agbára ìyẹn "Power Shift Movement" pé ipò Ààrẹ gbọdọ̀ wá láti ẹkùn Gúúsù orílẹ̀ èdè yìí lọ́dún 2023 nígbà tí wọ́n ṣe àbẹ̀wò sí i ní ọ́fíìsì rẹ̀ ní Akure. Nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ ẹgbẹ́ Afenifere, Jare Ajayi ní ẹgbẹ́ náà ti kọ orin àtìlẹyìn kín ọ̀rọ̀ tí Akeredolu sọ yìí èyí tí àwọn ẹgbẹ́ ilẹ̀ Árèwá méjì ìyẹn Arewa Consultative Forum (ACF) àti Coalition of Northern Groups (CNG) ti ń takò. Afenifere ní ipò Gómìnà Akeredolu wà ní ìbámu pẹ̀lú ìrètí àti ìfẹ́ àwọn ènìyàn ẹkùn ìwọ̀ oòrùn, ìlà oòrùn, àti ààrin gbùngùn gúúsù Nàìjíríà tí wọ́n parapọ̀ dá ẹgbẹ́ "South and Middle Belt Leadership Forum" kalẹ̀. Ajayi ní gbogbo àwọn aṣojú wọn wọ̀nyìí ló péjú síbi ìpàdé tí wọ́n ṣe pẹ̀lú gómìnà Akeredolu. Ó ní gbogbo àwọn ni àwọn jọ ni Nàìjíríà, ẹ̀yà kan kò sì gbọdọ̀ máa jẹ gàba lé àwọn yòókù. Ó fi kun pé ẹkùn Arewa ti lo ọdún mẹ́jọ tí Ààrẹ Muhammadu Buhari bá ti parí sáà rẹ̀ lórí àléfà, ó sì di dandan kí ipò náà padà sí ẹkùn gúúsù Nàìjíríà. Bákan náà ló rọ ACF àti CNG láti bá àwọn ènìyàn wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n máa ṣọ́ ìwà àti ọ̀rọ̀ wọn èyí tó le da omi àláfìà rú. Kíló ṣẹlẹ̀ gan an? Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹjọ, oṣù kejì ni Gómìnà Rotimi Akeredolu ní ipò Ààrẹ gbọdọ̀ wá láti ẹkùn Gúúsù orílẹ̀ èdè yìí lọ́dún 2023 à ti pé ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá mú olùdíje wá láti ẹkùn árèwá yóò fìdí rẹmi. Gómìnà Akeredolu, nígbà tó gbàlejò ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìṣípò agbára ìyẹn "Power Shift Movement" èyí tí alága wọn Dókítà Pogu Bitrus kó sòdí, sọ pé àwọn gómìnà gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà nínú àwọn ìpàdé àwọn ti fẹnukò pé ipò Ààrẹ gbọ́dọ̀ wá láti ẹkùn àwọn lọ́dún 2023. Báwo ni Arewa ṣe gba ọ̀rọ̀ yìí? ẹ̀wẹ̀, lọ́jọ́ rú ni àwọn agbẹnusọ ACF, Emmanuel Yewa àti CNG, Abdul-Azeez Suleiman nínú àtẹ̀jáde ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ju òkò ọ̀rọ̀ lu gómìnà Akeredolu pé kò fẹ́ràn àwọn ènìyàn ẹkùn árèwá. Yawe àti Suleiman ní ọ̀rọ̀ Akeredolu sọ yìí dàbí èyí tó fi ń dúnkokò mọ́ ẹkùn arewa ni
2023 elections: Afenifere ní ipò Ààrẹ gbọdọ̀ padà sí ẹkùn gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà lọ́dún tó ń bọ̀ Ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀ Yorùbá ti lùlù àtìlẹyìn fún ẹgbẹ́ àwọn gómìnà gúúsù ilẹ̀ gúúsù Nàìjíríà (SGF) lórí pé ipò Ààrẹ gbọdọ̀ wá láti ẹkùn Gúúsù orílẹ̀ èdè yìí lọ́dún 2023. Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹjọ, oṣù kejì ni Gómìnà Rotimi Akeredolu ti ìpínlẹ̀ Ondo tó jẹ́ alága SGF sọ fún àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìṣípò agbára ìyẹn "Power Shift Movement" pé ipò Ààrẹ gbọdọ̀ wá láti ẹkùn Gúúsù orílẹ̀ èdè yìí lọ́dún 2023 nígbà tí wọ́n ṣe àbẹ̀wò sí i ní ọ́fíìsì rẹ̀ ní Akure. Nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ ẹgbẹ́ Afenifere, Jare Ajayi ní ẹgbẹ́ náà ti kọ orin àtìlẹyìn kín ọ̀rọ̀ tí Akeredolu sọ yìí èyí tí àwọn ẹgbẹ́ ilẹ̀ Árèwá méjì ìyẹn Arewa Consultative Forum (ACF) àti Coalition of Northern Groups (CNG) ti ń takò. Afenifere ní ipò Gómìnà Akeredolu wà ní ìbámu pẹ̀lú ìrètí àti ìfẹ́ àwọn ènìyàn ẹkùn ìwọ̀ oòrùn, ìlà oòrùn, àti ààrin gbùngùn gúúsù Nàìjíríà tí wọ́n parapọ̀ dá ẹgbẹ́ "South and Middle Belt Leadership Forum" kalẹ̀. Ajayi ní gbogbo àwọn aṣojú wọn wọ̀nyìí ló péjú síbi ìpàdé tí wọ́n ṣe pẹ̀lú gómìnà Akeredolu. Ó ní gbogbo àwọn ni àwọn jọ ni Nàìjíríà, ẹ̀yà kan kò sì gbọdọ̀ máa jẹ gàba lé àwọn yòókù. Ó fi kun pé ẹkùn Arewa ti lo ọdún mẹ́jọ tí Ààrẹ Muhammadu Buhari bá ti parí sáà rẹ̀ lórí àléfà, ó sì di dandan kí ipò náà padà sí ẹkùn gúúsù Nàìjíríà. Bákan náà ló rọ ACF àti CNG láti bá àwọn ènìyàn wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n máa ṣọ́ ìwà àti ọ̀rọ̀ wọn èyí tó le da omi àláfìà rú. Kíló ṣẹlẹ̀ gan an? Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹjọ, oṣù kejì ni Gómìnà Rotimi Akeredolu ní ipò Ààrẹ gbọdọ̀ wá láti ẹkùn Gúúsù orílẹ̀ èdè yìí lọ́dún 2023 à ti pé ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá mú olùdíje wá láti ẹkùn árèwá yóò fìdí rẹmi. Gómìnà Akeredolu, nígbà tó gbàlejò ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìṣípò agbára ìyẹn "Power Shift Movement" èyí tí alága wọn Dókítà Pogu Bitrus kó sòdí, sọ pé àwọn gómìnà gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà nínú àwọn ìpàdé àwọn ti fẹnukò pé ipò Ààrẹ gbọ́dọ̀ wá láti ẹkùn àwọn lọ́dún 2023. Báwo ni Arewa ṣe gba ọ̀rọ̀ yìí? ẹ̀wẹ̀, lọ́jọ́ rú ni àwọn agbẹnusọ ACF, Emmanuel Yewa àti CNG, Abdul-Azeez Suleiman nínú àtẹ̀jáde ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ju òkò ọ̀rọ̀ lu gómìnà Akeredolu pé kò fẹ́ràn àwọn ènìyàn ẹkùn árèwá. Yawe àti Suleiman ní ọ̀rọ̀ Akeredolu sọ yìí dàbí èyí tó fi ń dúnkokò mọ́ ẹkùn arewa ni
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60361121
5sports
Omí pọ̀ ju ọkà lọ fún Unai Emery, ìfìdírẹ̀mi mí ló bade fún lọ́wọ́ Frankfurt
Ninu atẹjade ti Arsenal fi soju opo twitter wọn ni wọn ti kede ipinnu wọn bayii. Wọn ni àwọn gbe igbesẹ yii lataari gbogbo ijakulẹ ti Unai emery n ri paapaa lori idije awọn bọọlu ti Arsenal n gba ti to gẹ. Josh Kroenke lasiko to n sọrọ lorukọ igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ati Kroenke Sports and Entertainment so pe: "A dupẹ lọwọ Unai ati awọn akẹgbẹ rẹ pupọ nitori pe wọn gbiyanju lati da ogo Arsenal pada de ipele to yẹ ti a beere fun. A gbadura arinna kore fun wọn bi wọn ti n lọ." Ẹgbe Arsenal ti le Unai Emery leyin osu mejilelogun, to gba ise. Amo, Freddie Ljungberg to je igbakeji akonimoogba ni yoo ma sakoso fun igba yii naa. Ọrọ boya iṣẹ yoo bọ lọwọ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal Unai Emery tun fidi rinlẹ si lọkan awọn onwoye pẹlu bi ikọ rẹ ṣe fidirẹmi lọwọ Frankfurt ninu idije Europa League. Ayo meji si odo ni ẹgbẹ agbabọọlu naa fi gbewuro soju ikọ Unai Emery. Ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba sẹyin, eyi ni yoo jẹ igba kẹje ti wọn yoo pade ijakulẹ. Lẹnu lọọlọ yi, ẹnu ti n kun Unai Emery ti ọpọ si ti n reti igba ti wọn yoo fọwọ osi juwe ile fun un. Laipẹ yi ni ẹgbẹ Arsenal lawọn ti n fimu-finlẹ si ẹni ti wọn yoo fi paarọ rẹ ni eyi ti ireti si wa pe o ṣeeṣe ko jẹ akọnimọọgba ẹgbẹ Wolves, Nuno Espirito ni yoo gba ipo rẹ. Niṣe ni igbe ọọbi gba nu awọn alatilẹyin ẹgbẹ naa lẹyin ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Frankfurt ti oju opo Twitter si kun fun ikunsinu lori bi o ti ṣe n tukọ ẹgbẹ naa. Ọpọlọpọ gba pe iṣẹ rẹ ko dara to ni ẹgbẹ agbabọọlu naa ṣe n ri ijakulẹ
Omí pọ̀ ju ọkà lọ fún Unai Emery, ìfìdírẹ̀mi mí ló bade fún lọ́wọ́ Frankfurt Ninu atẹjade ti Arsenal fi soju opo twitter wọn ni wọn ti kede ipinnu wọn bayii. Wọn ni àwọn gbe igbesẹ yii lataari gbogbo ijakulẹ ti Unai emery n ri paapaa lori idije awọn bọọlu ti Arsenal n gba ti to gẹ. Josh Kroenke lasiko to n sọrọ lorukọ igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ati Kroenke Sports and Entertainment so pe: "A dupẹ lọwọ Unai ati awọn akẹgbẹ rẹ pupọ nitori pe wọn gbiyanju lati da ogo Arsenal pada de ipele to yẹ ti a beere fun. A gbadura arinna kore fun wọn bi wọn ti n lọ." Ẹgbe Arsenal ti le Unai Emery leyin osu mejilelogun, to gba ise. Amo, Freddie Ljungberg to je igbakeji akonimoogba ni yoo ma sakoso fun igba yii naa. Ọrọ boya iṣẹ yoo bọ lọwọ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal Unai Emery tun fidi rinlẹ si lọkan awọn onwoye pẹlu bi ikọ rẹ ṣe fidirẹmi lọwọ Frankfurt ninu idije Europa League. Ayo meji si odo ni ẹgbẹ agbabọọlu naa fi gbewuro soju ikọ Unai Emery. Ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba sẹyin, eyi ni yoo jẹ igba kẹje ti wọn yoo pade ijakulẹ. Lẹnu lọọlọ yi, ẹnu ti n kun Unai Emery ti ọpọ si ti n reti igba ti wọn yoo fọwọ osi juwe ile fun un. Laipẹ yi ni ẹgbẹ Arsenal lawọn ti n fimu-finlẹ si ẹni ti wọn yoo fi paarọ rẹ ni eyi ti ireti si wa pe o ṣeeṣe ko jẹ akọnimọọgba ẹgbẹ Wolves, Nuno Espirito ni yoo gba ipo rẹ. Niṣe ni igbe ọọbi gba nu awọn alatilẹyin ẹgbẹ naa lẹyin ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Frankfurt ti oju opo Twitter si kun fun ikunsinu lori bi o ti ṣe n tukọ ẹgbẹ naa. Ọpọlọpọ gba pe iṣẹ rẹ ko dara to ni ẹgbẹ agbabọọlu naa ṣe n ri ijakulẹ
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-50597425
5sports
FIFA Football Awards: Messi la Ronaldo, Van Dijk láti gba àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó pegedé jùlọ lágbayé
Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé wọn ti kede Lionel Messi gẹgẹ bii agbabọọlu FIFA to pegede julọ lagbaye. Messi to jẹ balogun ikọ orilẹede Argentina ati Barcelona n gba ami ẹyẹ naa fun igba kẹfa. Messi, Ronaldo ati Van Dijk ni awọn agbabọọẹu mẹta ti wọn yan fun ami ẹyẹ yii. Saaju ikede agbabọọlu to ku oju iwọn julọ lagbaye ni wọn ti kede olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp ni wọn yan gẹgẹ bii olukọni to pegede julọ. Awọn ami ẹyẹ miran ti wọn kede ni iwọnyii: 1.Allison Becker 1.Matthijs de Ligt 2.Sergio Ramos 3.Van Dijk 4.Marcelo 1.Luca Modric 2.Frenkie de Jong 3.Eden hazard 1.Kylian Mbappé 2.Lionel Messi
FIFA Football Awards: Messi la Ronaldo, Van Dijk láti gba àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó pegedé jùlọ lágbayé Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé wọn ti kede Lionel Messi gẹgẹ bii agbabọọlu FIFA to pegede julọ lagbaye. Messi to jẹ balogun ikọ orilẹede Argentina ati Barcelona n gba ami ẹyẹ naa fun igba kẹfa. Messi, Ronaldo ati Van Dijk ni awọn agbabọọẹu mẹta ti wọn yan fun ami ẹyẹ yii. Saaju ikede agbabọọlu to ku oju iwọn julọ lagbaye ni wọn ti kede olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp ni wọn yan gẹgẹ bii olukọni to pegede julọ. Awọn ami ẹyẹ miran ti wọn kede ni iwọnyii: 1.Allison Becker 1.Matthijs de Ligt 2.Sergio Ramos 3.Van Dijk 4.Marcelo 1.Luca Modric 2.Frenkie de Jong 3.Eden hazard 1.Kylian Mbappé 2.Lionel Messi
https://www.bbc.com/yoruba/49801046
3politics
Gbogbo ẹni tó bá ní ẹ̀rí wípé mo fi owó ra ìbò kó mú wá – Oyebanji
Gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní ipínlẹ̀ Ekiti, Abiodun Oyebanji ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti fún bí wọ́n ṣe jáde láti dìbò yan òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò máa tukọ̀ ìpínlẹ̀ náà fún mẹ́rin. Oyebanji nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ wí pé òun gba èsì ìdìbò ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 níbi àjọ INEC ti kéde rẹ̀ wípé òun ló gbégbá orókè wọlé. Oyebanji rọ gbogbo ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú òun nígbà tí wọ́n bá búra wọlé fún òun nínú oṣù Kẹwàá. Ó ní ó pọn dandan kí gbogbo àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti kí wọ́n fi ohùn ṣọ̀kan kí ìdàgbàsókè, àláfíà àti ìtẹ̀síwájú le bá ìpínlẹ̀ Ekiti. Bákan náà ló fi kun pé gbogbo àwọn iṣẹ́ ribiribi tí ìjọba tó wà ní orí àléfà tí òun ń gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ gúnlè ní òun yóò tẹ̀síwájú lé lórí. Bẹ́ẹ̀ náà ló ní gbogbo ìlérí tí òun ṣe lásìkò ìpolongo ìbò ni òun yóò ṣe àmúṣẹ, tó sì rọ àwọn ènìyàn láti kún ìjọba òun lọ́wọ́. Oyebanji ni gbogbo àwọn tí àwọn jọ díje dupò ni òun yóò kàn sí lójúnà àti mu nínú omi ìmọ̀ wọn kí ìpínlẹ̀ Ekiti le ní ìlọsíwájú tó yẹ. Ó ní òun àti àwọn ará ìlú ni àwọn yóò jọ ṣe ìjọba nítorí gbayawu ni ilẹ̀kùn òun yóò wà ní ṣíṣí kalẹ̀ fún wọn nítorí à ti mọ òun tí wọ́n bá ń fẹ́. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án àti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Party, APC wí pé owó ni wọ́n fi ra ìbò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn, Oyebanji ní ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀rí níbi tí òun bá ti ń fún ènìyàn lówó kó mu jáde. Ó ní òfin fi àyè gba gbogbo ẹni tó bá fẹ̀sùn kan ènìyàn láti fi ẹ̀rí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nítorí náà ni òun ṣe ń pe àwọn tó ;n gbé ìròyìn náà kiri níjà láti fi ẹ̀rí gbe ọ̀rọ̀ wọn lẹ́sẹ̀. Ẹgbẹ oṣelu APC ti jawe olubori ninu eto idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Ekiti lọjọ Abamẹta. Ṣaaju ni ẹni to n ṣoju fun ajọ eleto idibo, INEC, to se akojọpọ ati kokari esi ibo naa, Ọjọgbọn Kayode Oyebode Adebowale ti kọkọ n ka ibo naa. Gbagede ọọfisi INEC to wa lagbegbe New Iyin Road, niluu Ado Ekiti, ni isẹlẹ naa ti waye lalẹ ọjọ Abamẹta si afẹmọju ọjọ Aiku. Oludjije ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Biodun Oyebanji lo gbegba oroke ninu eto idibo naa. Nigba ti oludije ninu ẹgbẹ oṣelu SDP, Segun Oni n sare tete tẹle lẹyin lati se ipo keji, ti Bisi Kolawole ti ẹgbẹ oṣelu PDP si ṣe ipo kẹta ninu eto idibo ọhun. Iye apapọ ibo ti APC ni ni: 187,057 Ẹgbẹ oṣelu PDP ni apapọ ibo: 67,457 Nigba ti ẹgbẹ oṣelu SDP ni ibo: 82,211 Ijọba ibilẹ Ijero: Apapọ iye eeyan to fi orukọ silẹ 65,328\nApapọ iye oludibo 25103\nA 08\nADC 96\nADP 201\nAPC 13754\nLP 16\nNNPP 48\nNRN 17\nPDP 4897\nPRP 87\nSDP 5006\nYPP 59\nZLP 18 Èsì ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Emure rèé Iye eeyan to dibo: 14,509 Esi ibo: A 4 AAC 15 ADC 81 ADP 92 APC 7728 APGA 14 APN 16 APP 70 LP13 NNPP 13 NRN 19 PDP 2610 PRP 24 SDP 3446 YPP 45 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti southwest Iye awọn to forukọsilẹ lati dibo:53,713 Iye eeyan to dibo:19,982 A 3 AAC 22 ADC 100 ADP 195 APC 9679 APGA ASK APN 10 APP 170 LP 14 NNPP 30 NRN 33 PDP 4474 PRP 43 SDP 4577 YPP 41 ZLP 26 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ikere Ekiti Iye awọn to forukọsilẹ lati dibo:65, 661 Iye awọn to dibo: 24109 A 16 AAC 49 ADC 3764 ADP 310 APC 12086 APGA 25 APN 17 APP 49 LP 14 NNPP 47 NRM 10 PDP 3789 PRP 35 SDP 1943 YPP 38 ZLP 9 Wo èsì ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ileje meje níbí Iye awọn to forukọsilẹ lati dibo:18,791 Iye awọn to dibo: 8,439 A 04 AAC 09 ADC 216 ADP 47 APC 4357 APGA 04 APM 05 APP 41 LP 01 NNPP 06 NRM 06 PDP 1157 PRP 18 SDP 2344 YPP 04 ZLP 04 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Moba Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 53,257 Iye èèyàn tó dìbò: 20,743 A 13\nAAC 20\nADC 75 \nAPC 11609\nApga 11 \nAPM 11\nAPP 41\nLP 06\nNNPP 09\nNRM 05 \nPDP 3530 \nPRP 41\nSDP 4904\nZLP 08 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Efon Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 30,076 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 11,046 A 02 AAC 04 ADC 17 ADP 77 APC 4012 APGA 11 APM 05 APP 11 LP 09 NNPP 04 NRM 16 PDP 6303 PRP 20 SDP 339 YPP 07 ZLP 02 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti West Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 59,220 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 23,750 A 09 AAC 26 ADC 90 ADP 178 APC 15322 APGA 30 APM 15 APP 105 LP 5 NNPP 28 NRM 29 PDP 3386 PRP 34 SDP 3863 YPP 24 ZLP 24 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Irepodun Ifelodun Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 70,467 Iye èèyàn tó dìbò: 24,123 A 5 AAC 33 ADC 141 ADP 191 APC 13125 APGA 16 APM 20 APP 112 LP 9 NNPP 29 NRM 20 PDP 4712 PRP 33 SDP 5010 YPP 44 ZLP 15 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Oye Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 65,170 Iye èèyàn tó dìbò: 24,925 A 14 AAC 34 ADC 83 ADP 210 APC 13396 APGA 17 APM 29 APP 167 LP 12 NNPP 33 NRM 23 PDP 4122 PRP 84 SDP 5391 YPP 32 ZLP 19 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ido/Osi Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 57,780 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 23,848 A 05 AAC 20 ADC 88 ADP 155 APC 10321 APGA 20 APM 11 APP 107 LP 10 NNPP 52 NRM 31 PDP 2871 PRP 72 SDP 9489 YPP 32 ZLP 21 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ise oorun Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 46,712 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 17,534 A 04 AAC 14 ADC 82 ADP 145 APC 8074 APGA 22 APM 18 APP 126 LP NNPP 07 NRM 15 PDP 2588 PRP 60 SDP 5909 YPP 38 ZLP 19 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ado Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 179,088 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 50,592 A 49 AAC 67 ADC 415 ADP 728 APC 23831 APGA 70 APM 62 APP 448 LP 47 NNPP 83 NRM 58 PDP 7575 PRP 141 SDP 15214 YPP 125 ZLP 51 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ikole Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 71,690 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 30,470 A 11 AAC 34 ADC 114 ADP 484 APC 16417 APGA 33 APM 19 APP 148 LP 14 NNPP 37 NRM 20 PDP 6266 PRP 88 SDP 5736 YPP 47 ZLP 13 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Gbonyin Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 53,788 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 20,308 A 11 AAC 18 ADC 73 ADP 190 APC 11247 APGA 21 APM 19 APP 156 LP 05 NNPP 22 NRM 16 PDP 3947 PRP 41 SDP 4059 YPP 20 ZLP 22 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti East Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 61,360 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 24,024 A 08 AAC 012 ADC 162 ADP 198 APC 12099 APGA 25 APM 17 APP 147 LP 013 NNPP 30 NRM 29 PDP 5230 PRP 45 SDP 4982 YPP 49 ZLP 19
Gbogbo ẹni tó bá ní ẹ̀rí wípé mo fi owó ra ìbò kó mú wá – Oyebanji Gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní ipínlẹ̀ Ekiti, Abiodun Oyebanji ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti fún bí wọ́n ṣe jáde láti dìbò yan òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò máa tukọ̀ ìpínlẹ̀ náà fún mẹ́rin. Oyebanji nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ wí pé òun gba èsì ìdìbò ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 níbi àjọ INEC ti kéde rẹ̀ wípé òun ló gbégbá orókè wọlé. Oyebanji rọ gbogbo ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú òun nígbà tí wọ́n bá búra wọlé fún òun nínú oṣù Kẹwàá. Ó ní ó pọn dandan kí gbogbo àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti kí wọ́n fi ohùn ṣọ̀kan kí ìdàgbàsókè, àláfíà àti ìtẹ̀síwájú le bá ìpínlẹ̀ Ekiti. Bákan náà ló fi kun pé gbogbo àwọn iṣẹ́ ribiribi tí ìjọba tó wà ní orí àléfà tí òun ń gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ gúnlè ní òun yóò tẹ̀síwájú lé lórí. Bẹ́ẹ̀ náà ló ní gbogbo ìlérí tí òun ṣe lásìkò ìpolongo ìbò ni òun yóò ṣe àmúṣẹ, tó sì rọ àwọn ènìyàn láti kún ìjọba òun lọ́wọ́. Oyebanji ni gbogbo àwọn tí àwọn jọ díje dupò ni òun yóò kàn sí lójúnà àti mu nínú omi ìmọ̀ wọn kí ìpínlẹ̀ Ekiti le ní ìlọsíwájú tó yẹ. Ó ní òun àti àwọn ará ìlú ni àwọn yóò jọ ṣe ìjọba nítorí gbayawu ni ilẹ̀kùn òun yóò wà ní ṣíṣí kalẹ̀ fún wọn nítorí à ti mọ òun tí wọ́n bá ń fẹ́. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án àti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Party, APC wí pé owó ni wọ́n fi ra ìbò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn, Oyebanji ní ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀rí níbi tí òun bá ti ń fún ènìyàn lówó kó mu jáde. Ó ní òfin fi àyè gba gbogbo ẹni tó bá fẹ̀sùn kan ènìyàn láti fi ẹ̀rí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nítorí náà ni òun ṣe ń pe àwọn tó ;n gbé ìròyìn náà kiri níjà láti fi ẹ̀rí gbe ọ̀rọ̀ wọn lẹ́sẹ̀. Ẹgbẹ oṣelu APC ti jawe olubori ninu eto idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Ekiti lọjọ Abamẹta. Ṣaaju ni ẹni to n ṣoju fun ajọ eleto idibo, INEC, to se akojọpọ ati kokari esi ibo naa, Ọjọgbọn Kayode Oyebode Adebowale ti kọkọ n ka ibo naa. Gbagede ọọfisi INEC to wa lagbegbe New Iyin Road, niluu Ado Ekiti, ni isẹlẹ naa ti waye lalẹ ọjọ Abamẹta si afẹmọju ọjọ Aiku. Oludjije ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Biodun Oyebanji lo gbegba oroke ninu eto idibo naa. Nigba ti oludije ninu ẹgbẹ oṣelu SDP, Segun Oni n sare tete tẹle lẹyin lati se ipo keji, ti Bisi Kolawole ti ẹgbẹ oṣelu PDP si ṣe ipo kẹta ninu eto idibo ọhun. Iye apapọ ibo ti APC ni ni: 187,057 Ẹgbẹ oṣelu PDP ni apapọ ibo: 67,457 Nigba ti ẹgbẹ oṣelu SDP ni ibo: 82,211 Ijọba ibilẹ Ijero: Apapọ iye eeyan to fi orukọ silẹ 65,328\nApapọ iye oludibo 25103\nA 08\nADC 96\nADP 201\nAPC 13754\nLP 16\nNNPP 48\nNRN 17\nPDP 4897\nPRP 87\nSDP 5006\nYPP 59\nZLP 18 Èsì ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Emure rèé Iye eeyan to dibo: 14,509 Esi ibo: A 4 AAC 15 ADC 81 ADP 92 APC 7728 APGA 14 APN 16 APP 70 LP13 NNPP 13 NRN 19 PDP 2610 PRP 24 SDP 3446 YPP 45 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti southwest Iye awọn to forukọsilẹ lati dibo:53,713 Iye eeyan to dibo:19,982 A 3 AAC 22 ADC 100 ADP 195 APC 9679 APGA ASK APN 10 APP 170 LP 14 NNPP 30 NRN 33 PDP 4474 PRP 43 SDP 4577 YPP 41 ZLP 26 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ikere Ekiti Iye awọn to forukọsilẹ lati dibo:65, 661 Iye awọn to dibo: 24109 A 16 AAC 49 ADC 3764 ADP 310 APC 12086 APGA 25 APN 17 APP 49 LP 14 NNPP 47 NRM 10 PDP 3789 PRP 35 SDP 1943 YPP 38 ZLP 9 Wo èsì ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ileje meje níbí Iye awọn to forukọsilẹ lati dibo:18,791 Iye awọn to dibo: 8,439 A 04 AAC 09 ADC 216 ADP 47 APC 4357 APGA 04 APM 05 APP 41 LP 01 NNPP 06 NRM 06 PDP 1157 PRP 18 SDP 2344 YPP 04 ZLP 04 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Moba Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 53,257 Iye èèyàn tó dìbò: 20,743 A 13\nAAC 20\nADC 75 \nAPC 11609\nApga 11 \nAPM 11\nAPP 41\nLP 06\nNNPP 09\nNRM 05 \nPDP 3530 \nPRP 41\nSDP 4904\nZLP 08 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Efon Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 30,076 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 11,046 A 02 AAC 04 ADC 17 ADP 77 APC 4012 APGA 11 APM 05 APP 11 LP 09 NNPP 04 NRM 16 PDP 6303 PRP 20 SDP 339 YPP 07 ZLP 02 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti West Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 59,220 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 23,750 A 09 AAC 26 ADC 90 ADP 178 APC 15322 APGA 30 APM 15 APP 105 LP 5 NNPP 28 NRM 29 PDP 3386 PRP 34 SDP 3863 YPP 24 ZLP 24 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Irepodun Ifelodun Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 70,467 Iye èèyàn tó dìbò: 24,123 A 5 AAC 33 ADC 141 ADP 191 APC 13125 APGA 16 APM 20 APP 112 LP 9 NNPP 29 NRM 20 PDP 4712 PRP 33 SDP 5010 YPP 44 ZLP 15 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Oye Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 65,170 Iye èèyàn tó dìbò: 24,925 A 14 AAC 34 ADC 83 ADP 210 APC 13396 APGA 17 APM 29 APP 167 LP 12 NNPP 33 NRM 23 PDP 4122 PRP 84 SDP 5391 YPP 32 ZLP 19 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ido/Osi Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 57,780 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 23,848 A 05 AAC 20 ADC 88 ADP 155 APC 10321 APGA 20 APM 11 APP 107 LP 10 NNPP 52 NRM 31 PDP 2871 PRP 72 SDP 9489 YPP 32 ZLP 21 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ise oorun Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 46,712 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 17,534 A 04 AAC 14 ADC 82 ADP 145 APC 8074 APGA 22 APM 18 APP 126 LP NNPP 07 NRM 15 PDP 2588 PRP 60 SDP 5909 YPP 38 ZLP 19 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ado Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 179,088 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 50,592 A 49 AAC 67 ADC 415 ADP 728 APC 23831 APGA 70 APM 62 APP 448 LP 47 NNPP 83 NRM 58 PDP 7575 PRP 141 SDP 15214 YPP 125 ZLP 51 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ikole Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 71,690 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 30,470 A 11 AAC 34 ADC 114 ADP 484 APC 16417 APGA 33 APM 19 APP 148 LP 14 NNPP 37 NRM 20 PDP 6266 PRP 88 SDP 5736 YPP 47 ZLP 13 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Gbonyin Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 53,788 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 20,308 A 11 AAC 18 ADC 73 ADP 190 APC 11247 APGA 21 APM 19 APP 156 LP 05 NNPP 22 NRM 16 PDP 3947 PRP 41 SDP 4059 YPP 20 ZLP 22 Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti East Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 61,360 Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 24,024 A 08 AAC 012 ADC 162 ADP 198 APC 12099 APGA 25 APM 17 APP 147 LP 013 NNPP 30 NRM 29 PDP 5230 PRP 45 SDP 4982 YPP 49 ZLP 19
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cq5801ygdlxo
4religion
'Àwa Ebira tí wà ní Owo fún "Donkey years" ẹ má na ìka àbùkù sí wa lórí ìkọlù Kátólíìkì Owo'
"Bí Ọ́lọ́run bá ṣeé tí ọwọ wa tẹ àwọn tó páàyàn ní Ìjọ Kátólíìkì Owo, a ò lu jẹ̀jẹ̀rẹ̀ sí wọn lára ká tó pe agbófinró" Awọn Ebira Ondo ti sọrọ pe ki awọn eeyan ma na ika abuku si awọn lori ikọlu ijọ Katoliiki ilu Owo nipinlẹ Ondo to waye loṣu bii melo kan sẹyin. Olubadamọran tẹlẹri fun gomina ipinlẹ Ondo lori ọrọ to kan awọn ẹya Ebira, to n gbe ni ipinlẹ naa, Hassan Ahette ba BBC Yoruba sọrọ to ṣi ṣalaye iha ti awọn ẹya Ebira ni Ondo kọ si iṣẹlẹ to waye ni ijọ Katoliiki ilu Owo. Iṣẹlẹ naa jẹ eyi ti awọn to ṣekọlu sibẹ pa ọpọlọpọ eniyan. Eyi jẹ esi si ero awọn eeyan kaakiri ti wọn ro pe awọn eeyan Ebira lo ṣe ikọlu si ijọ Katoliiki Owo naa.
'Àwa Ebira tí wà ní Owo fún "Donkey years" ẹ má na ìka àbùkù sí wa lórí ìkọlù Kátólíìkì Owo' "Bí Ọ́lọ́run bá ṣeé tí ọwọ wa tẹ àwọn tó páàyàn ní Ìjọ Kátólíìkì Owo, a ò lu jẹ̀jẹ̀rẹ̀ sí wọn lára ká tó pe agbófinró" Awọn Ebira Ondo ti sọrọ pe ki awọn eeyan ma na ika abuku si awọn lori ikọlu ijọ Katoliiki ilu Owo nipinlẹ Ondo to waye loṣu bii melo kan sẹyin. Olubadamọran tẹlẹri fun gomina ipinlẹ Ondo lori ọrọ to kan awọn ẹya Ebira, to n gbe ni ipinlẹ naa, Hassan Ahette ba BBC Yoruba sọrọ to ṣi ṣalaye iha ti awọn ẹya Ebira ni Ondo kọ si iṣẹlẹ to waye ni ijọ Katoliiki ilu Owo. Iṣẹlẹ naa jẹ eyi ti awọn to ṣekọlu sibẹ pa ọpọlọpọ eniyan. Eyi jẹ esi si ero awọn eeyan kaakiri ti wọn ro pe awọn eeyan Ebira lo ṣe ikọlu si ijọ Katoliiki Owo naa.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/crgd6rgdqrno
3politics
EFCC Chairman: Adarí àjọ EFCC wà ni àláfíà, kò sí nǹkan tó ṣe , yóò padà sí ẹnu iṣẹ̀ rẹ̀ ni àìpẹ́- Agbẹnusọ EFCC
Ọ̀sán ọjọ́ àlàmísì ni ni ìròyìn kan pé adari àjọ tọ n gbọgun ti ìwà jẹgudújẹra Abdulrasheed Bawa lo jọ bi ẹni pé òyì kọ́ lásìkò tó n sọrọ̀ níbi ìpàdé kan ni Aso Rock. Ìròyìn sọ pé, wọ́n pèé síbi ètò kan ni Aso Rock sùgbọ́n lásíkò tí wọ́n pèé sórí gbàgede ló bẹ̀rl ọ̀rọ̀ rẹ tí o ní láti sọ, sùgbọ́n ni kété tó sọ̀rọ̀ tá tí ó sì pàdà sí àa[yé rẹ̀ ló subú sórí àga rẹ̀. Kíá náà ni àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ sáré rọ̀gbà yíi ka. Ẹ̀wẹ̀, àjọ tó n gbogun ti ìwà jẹgúdújẹrá (EFCC) náà tí fí àtẹ̀jáde kan síta pé, ayọ̀ àti aláíà ní ọ̀ga àwọn wà Bákan náà ni wọ́n fi kun nínú àtẹ̀jáde tí adári ètò ìròyìn àti ọ̀rọ̀ tó n lọ Wilson Uwujaren fi ọwọ́ sí lo tan imọlẹ ọ̀rọ̀ náà nípa ipò tí Bawa wa ní ìlú Abuja. Àtẹjáde náà sọ báyìí pé, : Ara ọ̀gá àwọn le koko ko si wàhálà kankan Ó ni, ó ṣe pàtàkì láti tan imọlẹ̀ sí ọ̀rọ̀ yìí nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lónìí, ọjọ́ kẹrindílógun, oṣù kẹsan, ọdún 2021 ni ilé ìjọba ni Abuja. Uwujaren ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé lásìkò tó n sọ̀rọ̀ ìkíni níbi ètò ayẹyẹ ọjọ́ idánimọ (National Identity Day), àsìkò yìí ló jọ bi éni pé, o rẹ̀ẹ́ díẹ̀, o sì lọ la'ti jòkó sí ààyè rẹ̀. "Wọ́n ti ṣe ìtajú tó yẹ fún , yóò sì padà sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀ láìpẹ́."
EFCC Chairman: Adarí àjọ EFCC wà ni àláfíà, kò sí nǹkan tó ṣe , yóò padà sí ẹnu iṣẹ̀ rẹ̀ ni àìpẹ́- Agbẹnusọ EFCC Ọ̀sán ọjọ́ àlàmísì ni ni ìròyìn kan pé adari àjọ tọ n gbọgun ti ìwà jẹgudújẹra Abdulrasheed Bawa lo jọ bi ẹni pé òyì kọ́ lásìkò tó n sọrọ̀ níbi ìpàdé kan ni Aso Rock. Ìròyìn sọ pé, wọ́n pèé síbi ètò kan ni Aso Rock sùgbọ́n lásíkò tí wọ́n pèé sórí gbàgede ló bẹ̀rl ọ̀rọ̀ rẹ tí o ní láti sọ, sùgbọ́n ni kété tó sọ̀rọ̀ tá tí ó sì pàdà sí àa[yé rẹ̀ ló subú sórí àga rẹ̀. Kíá náà ni àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ sáré rọ̀gbà yíi ka. Ẹ̀wẹ̀, àjọ tó n gbogun ti ìwà jẹgúdújẹrá (EFCC) náà tí fí àtẹ̀jáde kan síta pé, ayọ̀ àti aláíà ní ọ̀ga àwọn wà Bákan náà ni wọ́n fi kun nínú àtẹ̀jáde tí adári ètò ìròyìn àti ọ̀rọ̀ tó n lọ Wilson Uwujaren fi ọwọ́ sí lo tan imọlẹ ọ̀rọ̀ náà nípa ipò tí Bawa wa ní ìlú Abuja. Àtẹjáde náà sọ báyìí pé, : Ara ọ̀gá àwọn le koko ko si wàhálà kankan Ó ni, ó ṣe pàtàkì láti tan imọlẹ̀ sí ọ̀rọ̀ yìí nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lónìí, ọjọ́ kẹrindílógun, oṣù kẹsan, ọdún 2021 ni ilé ìjọba ni Abuja. Uwujaren ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé lásìkò tó n sọ̀rọ̀ ìkíni níbi ètò ayẹyẹ ọjọ́ idánimọ (National Identity Day), àsìkò yìí ló jọ bi éni pé, o rẹ̀ẹ́ díẹ̀, o sì lọ la'ti jòkó sí ààyè rẹ̀. "Wọ́n ti ṣe ìtajú tó yẹ fún , yóò sì padà sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀ láìpẹ́."
https://www.bbc.com/yoruba/58578815
4religion
Ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá yan olùdíje ààrẹ àti igbákejì rẹ̀ nínú ẹ̀sìn kan ṣoṣo yóò kùnà - CAN
Ẹgbẹ ọmọlẹyìn kristi lorileede Naijira CAN ti fariga pe awọn lodi si ki ẹgbẹ oloṣelu kankan yan oludije ipo ààrẹ ati igbakeji labẹ tíkẹ́ẹ̀tì ẹlẹsin kanna. Wọn ni eyikeyi ẹgbẹ to bá ṣe iru eleyi yoo kuna ni. Ọrọ yi jẹyọ ninu atẹjade kan ti  akọwe ẹgbẹ naa Joseph Bade Daramola fi sita. O ni awọn ki awọn to jawe Olubori ninu idije idibo abẹnu to yan oludije ipo ààrẹ labẹ asia ẹgbẹ ṣugbọn awọn fẹ fi to awọn ẹgbẹ yi leti pe patapata l'awọn tako yiyan Musulumi ati Musulumi tabi Kristeni ati Kristeni gẹgẹ bí aarẹ ati igbakeji Ààrẹ ninu tikẹẹti ẹgbẹ wọn ni  2023. Igba àkọkọ kọ ni yi ti CAN yoo maa fi ikilọ yi si'ta fawọn ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria. Ikilọ eleyi sí n waye lẹyìn ti iroyin gbòde pé oludije ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo ààrẹ Bola Ahmed Tinubu n gbero lati yan igbakeji musulumi. Ìkọ Tinubu ti sọ pe ko sí ootọ ninu iroyin boti lẹ jẹ pe ko ti sọ pato ẹni tí yoo yan. Ati Tinubu àti Atiku Abubakar l,oludije ipo ààrẹ labẹ àsìá ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party to jẹ ẹgbẹ alatako, musulumi láwọn mejeeji. Nítorí kini CAN ṣe fariga? Atẹjade lati ọdọ CAN mẹnu ba awọn alaye kan gẹgẹ bí eredi tàwọn ko fi faaye gba tikẹẹti ẹlẹsin kanna. Ninu ọrọ rẹ akọwe kan mu akawe awọn iṣẹlẹ to ti waye sẹyìn tó sì ni láwọn ìgbà tí ẹgbẹ oloṣelu yan oludije ẹlẹsin kanna nkan ko rọgbọ fawọn ọmọlẹyìn kristi ni Nàìjíríà. Ni paapa CAN ni iru igbesẹ yi yoo mu kí alaafia Naijiria ti ko f'ẹsẹ múlẹ daada tẹlẹ "wa nínú ewu nla" CAN sọ pe awọn oloṣelu lè máa ṣọ ọrọ oṣelu ṣugbọn awọn kò faramọ tikẹẹti ẹlẹsin kanna tori pe ẹgbẹ to bá ṣe bẹẹ yóò kùnà ní. "Eleyii kìí ṣe ọdún 1993" 1993 ti wọn mẹnu ba yi ni igba ti oludije ààrẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party ,MKO Abiola yan Baba Gana Kingibe gẹgẹ bi igbakeji rẹ tí aráàlú sí dibo fún wọn. Ninu àkọsílẹ itan òṣèlú eleyii lo fẹ ẹ jẹ igba kan táa rí ti tikẹẹti ẹlẹsin kanna waye. Laipẹ yi,Gómìnà ipinlẹ Kaduna Nasir El-Rufai yan igbakeji musulumi ti eleyi ko sí dùn mọ  awọn Kristiẹni ipinlẹ naa ninu. Gẹgẹ bi CAN ṣe sọ," koda ki a ní tikẹẹti Musulumi ati Kristiẹni, iya ṣi máa njẹ awọn ọmọlẹyìn Kristi ni Naijiria.Olorun nikan lo mọ iye àwọn Kristẹni tí wọn ti pa ti nkankan ko si ṣẹlẹ sí awọn to p'awọn tabi ki wọn sì pe wọn lẹjọ" Ni bayii CAN ti wa la kalẹ pe igbakeji ti Bola Tinubu ẹgbẹ APC bá yan gbọdọ jẹ Kristẹni lati ariwa Naijiria. Atiku Abubakar PDP naa gbọdọ yan igbakeji Kristẹni lati iha Guusu Naijiria. Peter Obi ẹgbẹ Labour Party naa sì gbọdọ yan igbakeji lati Ariwa Naijiria ko sí jẹ musulumi. Ohunkohun to ba yatọ sí eleyi gẹgẹ bi wọn ṣe sọ tunmọ sí pé àwọn ẹgbẹ yi ko nifẹ si isọkan ati alaafia Naijiria ni. Labẹ ofin ko si ohun tó takò pe ki oludije ààrẹ yan igbakeji to ba wu. Lọpọ ìgbà awọn oloṣelu maa n wo iwoye yiyan igbakeji ti yóò jẹ kí wọn lè gbegba oroke ninu idibo ṣaaju boya o jẹ ẹlẹsin kan tabi omiran. Nítorí pé Naijiria jẹ orileede ti ẹlẹya mẹya ati ẹlẹsinmẹsin,iru tikẹẹti ti ẹgbẹ ba yan maa n kopa ninu boya wọn yóò dé ori ipo. Amọ ṣa kò sí aridaju pe yiyan ẹlẹsin ọtọọtọ le mú kí ìṣèjọba mu anfaani ba araalu. Labẹ ìjọba tó kọjá ati eleyi to wa níbẹ ati musulumi ati Kristẹni ní ìnira n ba ni paapa lọwọ awọn agbesunmọmi ajinigbe ati awọn ti n dunkoko mọ alaafia orileede Naijiria. Ni eleyi to fẹẹ sunmọ ootọ, awọn to n ṣé àkóbá fún araalu yala nipa iwa ajẹbanu tabi akoso ti ko gunrege, ẹlẹsin musulumi ati Kristẹni lapapọ lo pọ ninu wọn. Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, ti fun gbogbo awọn to fẹ dije fun ipo aarẹ lọdun 2023, ni gbedeke lati yan igbakeji wọn. Alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, kede ninu atẹjade kan pe Ọjọru, ọjọ kẹtadindogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ni gbedeke fun wọn. Nigba ti tawọn gomina jẹ ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹfa. Ọjọgbọn Yakubu sọ pe ẹgbẹ kọọkan gbọdọ fi orukọ oludije wọn ranṣẹ titi ọjọ gbedeke naa, pẹlu orukọ igbakeji wọn. “Awọn to fẹ dupo aarẹ ati gomina gbọdọ fi orukọ wọn ranṣẹ pẹlu ti ẹni ti yoo jẹ igbakeji wọn. Lai ṣe bẹẹ, iyansipo wọn gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ wọn ko fẹsẹ mulẹ.” Bakan naa lo tun ṣalaye pe oju opo ayelujara ajọ INEC, ni wọn gbọdọ kọ gbogbo rẹ si, ki wọn o to ti oju opo naa pa ni aago mẹfa irọlẹ ọjọ gbedeke kọọkan. Titi di asiko yii, ko si oludije fun ipo aarẹ to tii kede orukọ igbakeji rẹ. Fun oludije ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Atiku Abubakar, ẹkun Gusu Naijiria ni ireti wa pe yoo ti yan igbakeji rẹ, nitori pe Ariwa ni oun ti wa. Bakan naa lo ri fun oludije ẹgbẹ New Nigeria Peoples Party (NNPP), Rabiu Kwankwaso. Ṣugbọn fun alatako rẹ lati inu ẹgbẹ osẹlu All Progressives Congress (APC), Bola Ahmed Tinubu, Ariwa ni ireti wa pe oun yoo ti yan tiẹ. Bakan naa ni fun oludije ẹgbẹ Labour Party, Peter Obi. Iha Gusu ni awọn mejeeji ti wa.
Ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá yan olùdíje ààrẹ àti igbákejì rẹ̀ nínú ẹ̀sìn kan ṣoṣo yóò kùnà - CAN Ẹgbẹ ọmọlẹyìn kristi lorileede Naijira CAN ti fariga pe awọn lodi si ki ẹgbẹ oloṣelu kankan yan oludije ipo ààrẹ ati igbakeji labẹ tíkẹ́ẹ̀tì ẹlẹsin kanna. Wọn ni eyikeyi ẹgbẹ to bá ṣe iru eleyi yoo kuna ni. Ọrọ yi jẹyọ ninu atẹjade kan ti  akọwe ẹgbẹ naa Joseph Bade Daramola fi sita. O ni awọn ki awọn to jawe Olubori ninu idije idibo abẹnu to yan oludije ipo ààrẹ labẹ asia ẹgbẹ ṣugbọn awọn fẹ fi to awọn ẹgbẹ yi leti pe patapata l'awọn tako yiyan Musulumi ati Musulumi tabi Kristeni ati Kristeni gẹgẹ bí aarẹ ati igbakeji Ààrẹ ninu tikẹẹti ẹgbẹ wọn ni  2023. Igba àkọkọ kọ ni yi ti CAN yoo maa fi ikilọ yi si'ta fawọn ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria. Ikilọ eleyi sí n waye lẹyìn ti iroyin gbòde pé oludije ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo ààrẹ Bola Ahmed Tinubu n gbero lati yan igbakeji musulumi. Ìkọ Tinubu ti sọ pe ko sí ootọ ninu iroyin boti lẹ jẹ pe ko ti sọ pato ẹni tí yoo yan. Ati Tinubu àti Atiku Abubakar l,oludije ipo ààrẹ labẹ àsìá ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party to jẹ ẹgbẹ alatako, musulumi láwọn mejeeji. Nítorí kini CAN ṣe fariga? Atẹjade lati ọdọ CAN mẹnu ba awọn alaye kan gẹgẹ bí eredi tàwọn ko fi faaye gba tikẹẹti ẹlẹsin kanna. Ninu ọrọ rẹ akọwe kan mu akawe awọn iṣẹlẹ to ti waye sẹyìn tó sì ni láwọn ìgbà tí ẹgbẹ oloṣelu yan oludije ẹlẹsin kanna nkan ko rọgbọ fawọn ọmọlẹyìn kristi ni Nàìjíríà. Ni paapa CAN ni iru igbesẹ yi yoo mu kí alaafia Naijiria ti ko f'ẹsẹ múlẹ daada tẹlẹ "wa nínú ewu nla" CAN sọ pe awọn oloṣelu lè máa ṣọ ọrọ oṣelu ṣugbọn awọn kò faramọ tikẹẹti ẹlẹsin kanna tori pe ẹgbẹ to bá ṣe bẹẹ yóò kùnà ní. "Eleyii kìí ṣe ọdún 1993" 1993 ti wọn mẹnu ba yi ni igba ti oludije ààrẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party ,MKO Abiola yan Baba Gana Kingibe gẹgẹ bi igbakeji rẹ tí aráàlú sí dibo fún wọn. Ninu àkọsílẹ itan òṣèlú eleyii lo fẹ ẹ jẹ igba kan táa rí ti tikẹẹti ẹlẹsin kanna waye. Laipẹ yi,Gómìnà ipinlẹ Kaduna Nasir El-Rufai yan igbakeji musulumi ti eleyi ko sí dùn mọ  awọn Kristiẹni ipinlẹ naa ninu. Gẹgẹ bi CAN ṣe sọ," koda ki a ní tikẹẹti Musulumi ati Kristiẹni, iya ṣi máa njẹ awọn ọmọlẹyìn Kristi ni Naijiria.Olorun nikan lo mọ iye àwọn Kristẹni tí wọn ti pa ti nkankan ko si ṣẹlẹ sí awọn to p'awọn tabi ki wọn sì pe wọn lẹjọ" Ni bayii CAN ti wa la kalẹ pe igbakeji ti Bola Tinubu ẹgbẹ APC bá yan gbọdọ jẹ Kristẹni lati ariwa Naijiria. Atiku Abubakar PDP naa gbọdọ yan igbakeji Kristẹni lati iha Guusu Naijiria. Peter Obi ẹgbẹ Labour Party naa sì gbọdọ yan igbakeji lati Ariwa Naijiria ko sí jẹ musulumi. Ohunkohun to ba yatọ sí eleyi gẹgẹ bi wọn ṣe sọ tunmọ sí pé àwọn ẹgbẹ yi ko nifẹ si isọkan ati alaafia Naijiria ni. Labẹ ofin ko si ohun tó takò pe ki oludije ààrẹ yan igbakeji to ba wu. Lọpọ ìgbà awọn oloṣelu maa n wo iwoye yiyan igbakeji ti yóò jẹ kí wọn lè gbegba oroke ninu idibo ṣaaju boya o jẹ ẹlẹsin kan tabi omiran. Nítorí pé Naijiria jẹ orileede ti ẹlẹya mẹya ati ẹlẹsinmẹsin,iru tikẹẹti ti ẹgbẹ ba yan maa n kopa ninu boya wọn yóò dé ori ipo. Amọ ṣa kò sí aridaju pe yiyan ẹlẹsin ọtọọtọ le mú kí ìṣèjọba mu anfaani ba araalu. Labẹ ìjọba tó kọjá ati eleyi to wa níbẹ ati musulumi ati Kristẹni ní ìnira n ba ni paapa lọwọ awọn agbesunmọmi ajinigbe ati awọn ti n dunkoko mọ alaafia orileede Naijiria. Ni eleyi to fẹẹ sunmọ ootọ, awọn to n ṣé àkóbá fún araalu yala nipa iwa ajẹbanu tabi akoso ti ko gunrege, ẹlẹsin musulumi ati Kristẹni lapapọ lo pọ ninu wọn. Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, ti fun gbogbo awọn to fẹ dije fun ipo aarẹ lọdun 2023, ni gbedeke lati yan igbakeji wọn. Alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, kede ninu atẹjade kan pe Ọjọru, ọjọ kẹtadindogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ni gbedeke fun wọn. Nigba ti tawọn gomina jẹ ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹfa. Ọjọgbọn Yakubu sọ pe ẹgbẹ kọọkan gbọdọ fi orukọ oludije wọn ranṣẹ titi ọjọ gbedeke naa, pẹlu orukọ igbakeji wọn. “Awọn to fẹ dupo aarẹ ati gomina gbọdọ fi orukọ wọn ranṣẹ pẹlu ti ẹni ti yoo jẹ igbakeji wọn. Lai ṣe bẹẹ, iyansipo wọn gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ wọn ko fẹsẹ mulẹ.” Bakan naa lo tun ṣalaye pe oju opo ayelujara ajọ INEC, ni wọn gbọdọ kọ gbogbo rẹ si, ki wọn o to ti oju opo naa pa ni aago mẹfa irọlẹ ọjọ gbedeke kọọkan. Titi di asiko yii, ko si oludije fun ipo aarẹ to tii kede orukọ igbakeji rẹ. Fun oludije ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Atiku Abubakar, ẹkun Gusu Naijiria ni ireti wa pe yoo ti yan igbakeji rẹ, nitori pe Ariwa ni oun ti wa. Bakan naa lo ri fun oludije ẹgbẹ New Nigeria Peoples Party (NNPP), Rabiu Kwankwaso. Ṣugbọn fun alatako rẹ lati inu ẹgbẹ osẹlu All Progressives Congress (APC), Bola Ahmed Tinubu, Ariwa ni ireti wa pe oun yoo ti yan tiẹ. Bakan naa ni fun oludije ẹgbẹ Labour Party, Peter Obi. Iha Gusu ni awọn mejeeji ti wa.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c80wr30kg06o
2health
Cubana NDLEA Arrest: NDLEA ní ó jọ pé egbògi olóró ni Cubuna fi tẹ́lẹ̀ ọlà rẹ̀
Ajọ to n gbogun ti lilo egbogi oloro lorilẹ ede Naijiria, NDLEA, lo fi ọrọ wa olowo nni Obi Iyiegbu ti gbogbo aye mọ si Obi Cubana lẹnu wo nipa pe o nii ṣe pẹlu tita egbogi oloro. Iyiegbu to jẹ alaga agbarijọ ileeṣẹ Cubana ni wọn fọrọ wa lẹnu wo ni olu ileeṣẹ ajọ NDLEA n'ilu Abuja fun bii wakati marun ko too di pe wọn tuu silẹ lati pada wa lọjọ miran. Oṣiṣẹ ileeṣẹ naa kan ti ko fẹ darukọ ara rẹ sọ fun BBC Yoruba pe awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA ni wọn ti n tanna wo Cubana ati gbogbo òwò rẹ boya o nii ṣe pẹlu gbigbe egbogi oloro. Iroyin to fẹsẹ rinlẹ to tẹ ileeṣẹ BBC News Yoruba lọwọ fihan pe ajọ NDLEA sọ pe awọn oniṣowo egbogi oloro mẹta ti wọn ti ran lẹwọn lorilẹ ede Malaysia, Naijiria ati India sanwo sinu asunwọn banki Cubana. Gbajumọ naa ni iroyin sọ pe wọn gba kí o lọ ile rẹ, ko le baa mu awọn iwe ti yoo fi ṣọwọ si ajọ NDLEA. Ni oṣu kọkanla ọdun to kọja, Iyiegbu lo wa ni pampe ajọ EFCC fun ọjọ mẹta lara iwadi sinu awọn ẹsun to jọmọ iṣowo mọku mọku ki wọn to yọnda rẹ lori wipe yoo maa fara han ni waju ajọ naa fun ifọrọwanilenuwo. A ò jẹ́ Ọba mọ́ o! A ṣetán láti padà sí ipò Olóyè tí a wà tẹ́lẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Olubadan - Lekan Balogun Háà, nǹkan ṣe mí! Ikú pa ọ̀kan lára àwọn aláànú mi - Yinka Ayefele Bí EFCC ṣe mú ayédèrú ọ̀gágun sọ́jà Bolarinwa tó tún ní ẹ̀sùn jìbìtì owó N270m
Cubana NDLEA Arrest: NDLEA ní ó jọ pé egbògi olóró ni Cubuna fi tẹ́lẹ̀ ọlà rẹ̀ Ajọ to n gbogun ti lilo egbogi oloro lorilẹ ede Naijiria, NDLEA, lo fi ọrọ wa olowo nni Obi Iyiegbu ti gbogbo aye mọ si Obi Cubana lẹnu wo nipa pe o nii ṣe pẹlu tita egbogi oloro. Iyiegbu to jẹ alaga agbarijọ ileeṣẹ Cubana ni wọn fọrọ wa lẹnu wo ni olu ileeṣẹ ajọ NDLEA n'ilu Abuja fun bii wakati marun ko too di pe wọn tuu silẹ lati pada wa lọjọ miran. Oṣiṣẹ ileeṣẹ naa kan ti ko fẹ darukọ ara rẹ sọ fun BBC Yoruba pe awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA ni wọn ti n tanna wo Cubana ati gbogbo òwò rẹ boya o nii ṣe pẹlu gbigbe egbogi oloro. Iroyin to fẹsẹ rinlẹ to tẹ ileeṣẹ BBC News Yoruba lọwọ fihan pe ajọ NDLEA sọ pe awọn oniṣowo egbogi oloro mẹta ti wọn ti ran lẹwọn lorilẹ ede Malaysia, Naijiria ati India sanwo sinu asunwọn banki Cubana. Gbajumọ naa ni iroyin sọ pe wọn gba kí o lọ ile rẹ, ko le baa mu awọn iwe ti yoo fi ṣọwọ si ajọ NDLEA. Ni oṣu kọkanla ọdun to kọja, Iyiegbu lo wa ni pampe ajọ EFCC fun ọjọ mẹta lara iwadi sinu awọn ẹsun to jọmọ iṣowo mọku mọku ki wọn to yọnda rẹ lori wipe yoo maa fara han ni waju ajọ naa fun ifọrọwanilenuwo. A ò jẹ́ Ọba mọ́ o! A ṣetán láti padà sí ipò Olóyè tí a wà tẹ́lẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Olubadan - Lekan Balogun Háà, nǹkan ṣe mí! Ikú pa ọ̀kan lára àwọn aláànú mi - Yinka Ayefele Bí EFCC ṣe mú ayédèrú ọ̀gágun sọ́jà Bolarinwa tó tún ní ẹ̀sùn jìbìtì owó N270m
https://www.bbc.com/yoruba/59991954
4religion
Taribo West: Àwọn aláìní ní Italy ní mò ń fi owó ìjọ mi ràn lọ́wọ́
Ilumọọka agbabọọlu ọmọ Naijiria to ti di ajihinrere bayii, Taribo West ti salaye lori bo se n gba awọn ọmọ Naijiria, to lọ se asẹwo lorilẹede Italy, silẹ. Agbabọọlu tẹlẹ naa, lasiko to n ba akọroyin Punch sọrọ ni ọpọ awọn ọmọ ilẹ yii ti ko rile gbe, atawọn asẹwo to wa nilu Milan ni oun n se iranlọwọ fun. Taribo ni ijọ oun, The Storm Miracle Ministry of All Nations, ni oun n lo lati tọ awọn eeyan naa sọna nipa igbe aye rere to yẹ ki wọn gbe. "Ọlọrun lo sọ fun wa pe ka lo ohun gbogbo ta ba ri ko jọ lati inu owo to n wọle fun wa, fi mu igbe aye dẹrun fawọn eeyan to ku diẹ kaa to fun. Bakan naa, gbogbo awọn eeyan ti awujọ ti ropin pe ko le se rere nitori ko rọrun lati gbe nilẹ Yuroopu, o dabi ilẹ awọn to n se atipo ọrọ aje ni." Taribo West fikun pe ọpọ awọn eeyan ti ijọ oun ti se iranlọwọ fun, tawọn si tun doola ẹmi wọn loke okun, si ni oun maa n kan si. Ijọba orilẹede Italy ti fagile faani ti wọn fun ọmọ orilẹede Naijiria kan to n gba ilẹ awọn adugbo kọọkan lai gba aṣẹ. Iroyin sọ pe ni ilu Venice ni ọmọ ọkunrin naa ti n gba ilẹ adugbo ti igbimọ alaṣẹ to wa nibẹ si ni ko gba aṣẹ ko to maa gba a. Ni ọlọpaa agbegbe Mestre lẹba Venice ba wọn ọn ni faini to fẹrẹẹ to $400 (iyẹn nkan bii N144,000). Lẹyin ọpọlọpọ ikun sinu latọdọ awn ara adugbo, awọn alaṣẹ gba pe awọn ti fun arakunrin naa ni ijiya to pọ ju. O ti di ohun to wọpọ ki awọn arinrinajo to lọ si orilẹede italy maa gba idọti awọn adugbo orilẹede naa. Wọn ni o pe awọn lati lọwọ si idagbasoke agbegbe naa ju ki awọn maa tọrọ owo kiri lọ. Ṣugbọn awọn ọlọpaa agbegbe fi ẹsun kan ẹni ọdun mọkandinlọgbọn naa ti orukọ rẹ n jẹ Monday pe o n tọju adugbo lai gba aṣẹ lọwọ awọn alakoso ibẹ. Agbẹjọro kan, Matteo D'Angelo to da eto iranwọ fun Ọgbẹni Monday silẹ lori ayelujara lati san faani rẹ sọ pe ijiya ti wọn fun un ko boju mu rara. Iroyin sọ pe Ọgbẹni D'Angelo ko owo ti wọn ko jọ lori ipolongo ori ayelujara fun Ọgbẹni Monday lati fi di iya ti awọn ọlọpaa fi jẹ ẹ.
Taribo West: Àwọn aláìní ní Italy ní mò ń fi owó ìjọ mi ràn lọ́wọ́ Ilumọọka agbabọọlu ọmọ Naijiria to ti di ajihinrere bayii, Taribo West ti salaye lori bo se n gba awọn ọmọ Naijiria, to lọ se asẹwo lorilẹede Italy, silẹ. Agbabọọlu tẹlẹ naa, lasiko to n ba akọroyin Punch sọrọ ni ọpọ awọn ọmọ ilẹ yii ti ko rile gbe, atawọn asẹwo to wa nilu Milan ni oun n se iranlọwọ fun. Taribo ni ijọ oun, The Storm Miracle Ministry of All Nations, ni oun n lo lati tọ awọn eeyan naa sọna nipa igbe aye rere to yẹ ki wọn gbe. "Ọlọrun lo sọ fun wa pe ka lo ohun gbogbo ta ba ri ko jọ lati inu owo to n wọle fun wa, fi mu igbe aye dẹrun fawọn eeyan to ku diẹ kaa to fun. Bakan naa, gbogbo awọn eeyan ti awujọ ti ropin pe ko le se rere nitori ko rọrun lati gbe nilẹ Yuroopu, o dabi ilẹ awọn to n se atipo ọrọ aje ni." Taribo West fikun pe ọpọ awọn eeyan ti ijọ oun ti se iranlọwọ fun, tawọn si tun doola ẹmi wọn loke okun, si ni oun maa n kan si. Ijọba orilẹede Italy ti fagile faani ti wọn fun ọmọ orilẹede Naijiria kan to n gba ilẹ awọn adugbo kọọkan lai gba aṣẹ. Iroyin sọ pe ni ilu Venice ni ọmọ ọkunrin naa ti n gba ilẹ adugbo ti igbimọ alaṣẹ to wa nibẹ si ni ko gba aṣẹ ko to maa gba a. Ni ọlọpaa agbegbe Mestre lẹba Venice ba wọn ọn ni faini to fẹrẹẹ to $400 (iyẹn nkan bii N144,000). Lẹyin ọpọlọpọ ikun sinu latọdọ awn ara adugbo, awọn alaṣẹ gba pe awọn ti fun arakunrin naa ni ijiya to pọ ju. O ti di ohun to wọpọ ki awọn arinrinajo to lọ si orilẹede italy maa gba idọti awọn adugbo orilẹede naa. Wọn ni o pe awọn lati lọwọ si idagbasoke agbegbe naa ju ki awọn maa tọrọ owo kiri lọ. Ṣugbọn awọn ọlọpaa agbegbe fi ẹsun kan ẹni ọdun mọkandinlọgbọn naa ti orukọ rẹ n jẹ Monday pe o n tọju adugbo lai gba aṣẹ lọwọ awọn alakoso ibẹ. Agbẹjọro kan, Matteo D'Angelo to da eto iranwọ fun Ọgbẹni Monday silẹ lori ayelujara lati san faani rẹ sọ pe ijiya ti wọn fun un ko boju mu rara. Iroyin sọ pe Ọgbẹni D'Angelo ko owo ti wọn ko jọ lori ipolongo ori ayelujara fun Ọgbẹni Monday lati fi di iya ti awọn ọlọpaa fi jẹ ẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49835763
3politics
Risikat Azeez: Aya gómìnà tún fẹ́ gba sọ́ọ́bù, ra ọjà fún obìnrin olójú búlúù
Ojo oriire si n rọ siwaju fun idile Risikat Oloju Buluu ati ọkọ rẹ, Abdulwasiu pẹlu awọn ọmọ wọn. Idi ni pe aya gomina ipinlẹ Kwara, Olufolake Abdulrazaq, to ti tẹwọgba ọrọ wọn lati ilẹ ko tii jawọ nibẹ, to si tun n se wsn loore siwaju lọ. Nibayii, lẹyin ayẹyẹ yigi ti wọn so lọjọ Satide, aya gomina ti gba ile fun wọn lati maa gbe lọtọ yatọ si ile mọlẹbi. Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, akọwe iroyin si aya gomina, Yinka Adeniyi sisọ loju rẹ fawọn akọroyin pe, lati ipasẹ ẹgbẹ alaanu ti aya Abdulrazak da silẹ, ni eyi ti see se. Ẹgbẹ alaanu naa, to pe ni Ajike Support Grouplo gba ile filaati oniyara meji fun idile naa laarin igboro ilu Ilorin. O fikun pe ọjọ Ẹti to kọja ni wọn fun tọkọtaya naa ni kọkọrọ ile naa, nigba to ku ọla ti wọn yoo so yigi. Bakan naa lo ni adugbo tawọn ẹbi ọhun fẹ ni wọn gba ile naa si fun wọn. Awọn eto ti aya gomina ni fun Risikat ati ọkọ rẹ wa nipele ipele, a tun fẹ gba sọọbu fun obinrin oloju buluu naa lati maa ta oogun to kọ isẹ rẹ. A lero lati san owo ile ati owo sọọbu rẹ papọ ni, amọ a gbọ pe ẹlomiran ti gba sọọbu ta fẹ sanwo rẹ naa, idi ree ta fi sanwo ile nikan, ta si ni ki obinrin naa lọ wa sọọbu miran." Akọwe iroyin aya gomina tẹsiwaju pe lẹyin eyi ni wọn yoo gba iwe asẹ lati maa ta oogun fun obinrin naa, ti wọn yoo si ra oogun kun inu sọọbu rẹ fun tita. A wa n ki Risikat ati ọkọ rẹ pe wọn ku oriire ayọ igbeyawo, Ọlọrun yoo se wọn ni ọrẹ ara wọn. Loni, ọjọ Satide, ọjọ karun un, oṣu kẹsan an ni Baba Kausara àti Iya Kausara di ara kan naa bii lọkọlaya ninu ẹsin Islam ni Ilorin ni ipinlẹ Kwara. Se ẹ ranti ọrọ Risikat ati Wasiu ọkọ rẹ nitori oju bulu aya ati ọmọ rẹ meji? Iroyin ni Ilorin Emirate Dev. Progressive Union lo ṣagbatẹru Nikkah naa laarọ yii. Ni ọkọ ba ti mọ oju aya tan, Ki gbogbo alarina yẹba lo ku. Lawọn Aafa nlanla ba kuku so yigi Iya Kausara ati Baba Kausara o Ni awọn alarinna ba ṣetan ati yẹba fun tọkọ taya. Eyi lo tun fidi imọran awọn agba Yoruba mulẹ pe iwọnba leeyan n da si ọrọ lọkọlaya mọ nitori.... Abi ẹ o riṣẹ Olorun bi? Ero peju sibẹ lati ba Risikat ati Wasiu yọ ni Ilọrin ni ipinlẹ Kwara ni aarin gbungbun Naijiria. Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin? Ọba Ilorin ló pàṣẹ pé kí ń padà sọ́dọ̀ ọkọ mi - Risikat olójú búlúù Ilé wa ni mo ṣì wà, èmi kò tíì padà sọ́dọ̀ Bàbá Kaosara Arabinrin Risikat Azeez ti ọpọ eeyan mọ si oloju buluu, naa ti fesi lori awọn ohun ti ọkọ rẹ ba BBC Yoruba sọ l‘Ọ́jọbọ. Bẹẹ ba gbagbe, a mu iroyin wa fun yin pe ọkọ Risikat Abdulwasiu Azeez ni oun ati aya oun ti pada sọdọ ara awọn, ti awọn si ti jọ n se mukẹẹkẹ. Sugbọn ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu wa ni aarọ ọjọ Ẹti, Risikat ni oun ati baba Kaosara dijọ ya fọto papọ ni, ile awọn si ni oun si wa. "Rara o, wọn so yigi o, ile wa ni mo wa. Ohun ti mo kan ri nibẹ ni pe aya gomina Kwara ran awọn eeyan wa pe awọn fẹ ka pari aawọ to wa laarin wa, ka si maa sọrọ sira wa. O tan o, nnkan ti wọn wa fun niyẹn. Risikat fikun pe, nigba to ya ni wọn tun ni ki eeyan kan wa wọn oun ati ọkọ oun, ti yoo ba awọn ran asọ wa, ti onitọun si gbe ankoo naa wa ni ọjọ keji. "Nigba to di Ọjọru, ni wọn ni ka ko asọ wa dani, ti wọn si ni ki wọn se oju mi loge fun mi nibudo ẹkọsẹ asaraloge ti mo ti n kọsẹ. Ati ibẹ ni ọga mi ti gbe mi lọ si ile ijọba, a debẹ, ni wọn ba n ya fọto fun wa, ohun ta ri naa nuu." Risikat fikun pe lootọ ni aya gomina n sọ pe ki awọn mejeeji pari ija, ki awọn si maa sọrọ si ara awọn, ti wọn si ya fọto fun awọn. Nigba ti BBC Yoruba bi iya Kaosara leere pe se lootọ lo ti n lọ sun sile ọkọ rẹ gẹgẹ bi ọkọ rẹ ti sọ fun wa, o dahun pe: "Mo fi Ọlọrun Ọba bura, ko si ohun to jọọ, ile wa ni mo wa, n ko si lọ sile ọdọ rẹ" Lori ipalẹmọ lati tun yigi so, Risikat ni ọba Ilọrin ti ran awọn eeyan wa lati ba awọn pari ija, to si ni wọn ti n pari rẹ lọwọ. "A ko tii mu ọjọ iyawo, amọ wọn saa fẹ se, ki wa ni mo fẹ se? Ọba Ilọrin sọ pe ohun ti oun yoo se niyẹn, oun gbẹsẹ le." Amọ nigba taa bii pe ki lo fẹ ki wọn seto, ko to pada sọdọ ọkọ rẹ, Risikat ni ti wọn ba pari ija tan laarin awọn mejeeji, ko sẹni ti yoo ya si ọdọ awọn mọ. "Ko sẹni to sọrọ lori ọrọ isẹ mi mọ, mo si fẹ ki wọn mojuto ọrọ ile iwe awọn ọmọ mi, isẹ temi naa, bẹẹ ni skọ mi gan ko ni isẹ to duro re." Arakunrin Abdulwasiu Ọlọmọyọyọ, tii se ọkọ Risikatu Azeez, arabinrin oloju buluu nilu Ilorin, ti fi idunnu ati ayọ rẹ han fun awọn ọmọ naijiria lori aayan ti wọn ko lati jẹ ki ija to wa laarin oun ati iyawo rẹ pari. Bakan naa ni Abdulwasiu, ti ọpọ eeyan tun mọ si baba Kaosara tun dupẹ pupọ lọwọ ileesẹ iroyin BBC Yoruba fun atilẹyin wa lori ọrọ naa ati ibi taa ba de, eyi to ni apẹrẹ rere. Ọkọ Risikat oloju buluu naa ko sai tun se sadankata si aya gomina ipinlẹ Kwara, fun iranwọ to n se lati ri pe idile oun pada toro pẹlu itọju to n se fun wọn. Amọ sa, Abdulwasiu wa fidi rẹ mulẹ pe laipẹ laijinna, oun ati iyawo oun yoo tun tun yigi so, ti idile oun yoo si pada duro re. Saaju la ti mu wa fun yin pe Abdul Wasiu ti sọ fun ileeṣẹ BBC Yoruba pe ni nibayi, ija ti pari laarin oun ati iyawo rẹ. ''Inu mi dun pupọ. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun ati awọn ọmọ Naijiria fun aduroti wọn'' O ṣalaye pe lọdọ Risikatu loun ti kuro laarọ yii ati pe ko ni pẹ ti awọn yoo fi tun ṣe yigi pada'' Laipẹ yii ni awọn eeyan n beere boya awọn mejeeji yoo pari ija laarin ara wọn. Koda iyawo Gomina ipinlẹ Kwara sọ wipe, oun yoo gbiyanju lati pari ija laarin awọn mejeeji. Ninu ohun ta ri gbọ lẹnu Baba Kaosara bakan naa o sọ pe, iyawo Gomina lo ba awọn pari ija naa ,ti o si tun ṣatọkun bi wọn ti ṣe jijọ ya aworan papọ. Nigba ti BBC Yoruba bi Abdulwasiu pe ki ni yoo sẹlẹ lẹyin ti wọn ba tun yigi se, ti aya rẹ si tun bi ọmọ oloju bulu, baba Kaosara dahun pe ọmọ oloju gan ni oun n tọrọ lọwọ Ọlọrun bayii. "Inu mi yoo dun pupọ ta ba tun bi ọmọ ti oju rẹ yoo bulu, koda, ki ni mo fẹ fi ọmọ olju funfun se mọ, mo tiẹ n gbadura pe gbogbo ọmọ ti Ọlọrun yoo ba fun mi siwaju, ki wọn jẹ oloju bulu." Abdulwasiu ti wa kesi awọn ọmọ Naijiria lati ṣe iranwọ fun ohun ni[pa ọna iṣẹ lati le fi tọju mọlẹbi rẹ. O sọ pe ko si iṣẹ kankan lọwọ oun bayii, toun si n beere iranwọ lọdọ awọn araalu lati se atọna bi oun yoo se ri isẹ.
Risikat Azeez: Aya gómìnà tún fẹ́ gba sọ́ọ́bù, ra ọjà fún obìnrin olójú búlúù Ojo oriire si n rọ siwaju fun idile Risikat Oloju Buluu ati ọkọ rẹ, Abdulwasiu pẹlu awọn ọmọ wọn. Idi ni pe aya gomina ipinlẹ Kwara, Olufolake Abdulrazaq, to ti tẹwọgba ọrọ wọn lati ilẹ ko tii jawọ nibẹ, to si tun n se wsn loore siwaju lọ. Nibayii, lẹyin ayẹyẹ yigi ti wọn so lọjọ Satide, aya gomina ti gba ile fun wọn lati maa gbe lọtọ yatọ si ile mọlẹbi. Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, akọwe iroyin si aya gomina, Yinka Adeniyi sisọ loju rẹ fawọn akọroyin pe, lati ipasẹ ẹgbẹ alaanu ti aya Abdulrazak da silẹ, ni eyi ti see se. Ẹgbẹ alaanu naa, to pe ni Ajike Support Grouplo gba ile filaati oniyara meji fun idile naa laarin igboro ilu Ilorin. O fikun pe ọjọ Ẹti to kọja ni wọn fun tọkọtaya naa ni kọkọrọ ile naa, nigba to ku ọla ti wọn yoo so yigi. Bakan naa lo ni adugbo tawọn ẹbi ọhun fẹ ni wọn gba ile naa si fun wọn. Awọn eto ti aya gomina ni fun Risikat ati ọkọ rẹ wa nipele ipele, a tun fẹ gba sọọbu fun obinrin oloju buluu naa lati maa ta oogun to kọ isẹ rẹ. A lero lati san owo ile ati owo sọọbu rẹ papọ ni, amọ a gbọ pe ẹlomiran ti gba sọọbu ta fẹ sanwo rẹ naa, idi ree ta fi sanwo ile nikan, ta si ni ki obinrin naa lọ wa sọọbu miran." Akọwe iroyin aya gomina tẹsiwaju pe lẹyin eyi ni wọn yoo gba iwe asẹ lati maa ta oogun fun obinrin naa, ti wọn yoo si ra oogun kun inu sọọbu rẹ fun tita. A wa n ki Risikat ati ọkọ rẹ pe wọn ku oriire ayọ igbeyawo, Ọlọrun yoo se wọn ni ọrẹ ara wọn. Loni, ọjọ Satide, ọjọ karun un, oṣu kẹsan an ni Baba Kausara àti Iya Kausara di ara kan naa bii lọkọlaya ninu ẹsin Islam ni Ilorin ni ipinlẹ Kwara. Se ẹ ranti ọrọ Risikat ati Wasiu ọkọ rẹ nitori oju bulu aya ati ọmọ rẹ meji? Iroyin ni Ilorin Emirate Dev. Progressive Union lo ṣagbatẹru Nikkah naa laarọ yii. Ni ọkọ ba ti mọ oju aya tan, Ki gbogbo alarina yẹba lo ku. Lawọn Aafa nlanla ba kuku so yigi Iya Kausara ati Baba Kausara o Ni awọn alarinna ba ṣetan ati yẹba fun tọkọ taya. Eyi lo tun fidi imọran awọn agba Yoruba mulẹ pe iwọnba leeyan n da si ọrọ lọkọlaya mọ nitori.... Abi ẹ o riṣẹ Olorun bi? Ero peju sibẹ lati ba Risikat ati Wasiu yọ ni Ilọrin ni ipinlẹ Kwara ni aarin gbungbun Naijiria. Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin? Ọba Ilorin ló pàṣẹ pé kí ń padà sọ́dọ̀ ọkọ mi - Risikat olójú búlúù Ilé wa ni mo ṣì wà, èmi kò tíì padà sọ́dọ̀ Bàbá Kaosara Arabinrin Risikat Azeez ti ọpọ eeyan mọ si oloju buluu, naa ti fesi lori awọn ohun ti ọkọ rẹ ba BBC Yoruba sọ l‘Ọ́jọbọ. Bẹẹ ba gbagbe, a mu iroyin wa fun yin pe ọkọ Risikat Abdulwasiu Azeez ni oun ati aya oun ti pada sọdọ ara awọn, ti awọn si ti jọ n se mukẹẹkẹ. Sugbọn ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu wa ni aarọ ọjọ Ẹti, Risikat ni oun ati baba Kaosara dijọ ya fọto papọ ni, ile awọn si ni oun si wa. "Rara o, wọn so yigi o, ile wa ni mo wa. Ohun ti mo kan ri nibẹ ni pe aya gomina Kwara ran awọn eeyan wa pe awọn fẹ ka pari aawọ to wa laarin wa, ka si maa sọrọ sira wa. O tan o, nnkan ti wọn wa fun niyẹn. Risikat fikun pe, nigba to ya ni wọn tun ni ki eeyan kan wa wọn oun ati ọkọ oun, ti yoo ba awọn ran asọ wa, ti onitọun si gbe ankoo naa wa ni ọjọ keji. "Nigba to di Ọjọru, ni wọn ni ka ko asọ wa dani, ti wọn si ni ki wọn se oju mi loge fun mi nibudo ẹkọsẹ asaraloge ti mo ti n kọsẹ. Ati ibẹ ni ọga mi ti gbe mi lọ si ile ijọba, a debẹ, ni wọn ba n ya fọto fun wa, ohun ta ri naa nuu." Risikat fikun pe lootọ ni aya gomina n sọ pe ki awọn mejeeji pari ija, ki awọn si maa sọrọ si ara awọn, ti wọn si ya fọto fun awọn. Nigba ti BBC Yoruba bi iya Kaosara leere pe se lootọ lo ti n lọ sun sile ọkọ rẹ gẹgẹ bi ọkọ rẹ ti sọ fun wa, o dahun pe: "Mo fi Ọlọrun Ọba bura, ko si ohun to jọọ, ile wa ni mo wa, n ko si lọ sile ọdọ rẹ" Lori ipalẹmọ lati tun yigi so, Risikat ni ọba Ilọrin ti ran awọn eeyan wa lati ba awọn pari ija, to si ni wọn ti n pari rẹ lọwọ. "A ko tii mu ọjọ iyawo, amọ wọn saa fẹ se, ki wa ni mo fẹ se? Ọba Ilọrin sọ pe ohun ti oun yoo se niyẹn, oun gbẹsẹ le." Amọ nigba taa bii pe ki lo fẹ ki wọn seto, ko to pada sọdọ ọkọ rẹ, Risikat ni ti wọn ba pari ija tan laarin awọn mejeeji, ko sẹni ti yoo ya si ọdọ awọn mọ. "Ko sẹni to sọrọ lori ọrọ isẹ mi mọ, mo si fẹ ki wọn mojuto ọrọ ile iwe awọn ọmọ mi, isẹ temi naa, bẹẹ ni skọ mi gan ko ni isẹ to duro re." Arakunrin Abdulwasiu Ọlọmọyọyọ, tii se ọkọ Risikatu Azeez, arabinrin oloju buluu nilu Ilorin, ti fi idunnu ati ayọ rẹ han fun awọn ọmọ naijiria lori aayan ti wọn ko lati jẹ ki ija to wa laarin oun ati iyawo rẹ pari. Bakan naa ni Abdulwasiu, ti ọpọ eeyan tun mọ si baba Kaosara tun dupẹ pupọ lọwọ ileesẹ iroyin BBC Yoruba fun atilẹyin wa lori ọrọ naa ati ibi taa ba de, eyi to ni apẹrẹ rere. Ọkọ Risikat oloju buluu naa ko sai tun se sadankata si aya gomina ipinlẹ Kwara, fun iranwọ to n se lati ri pe idile oun pada toro pẹlu itọju to n se fun wọn. Amọ sa, Abdulwasiu wa fidi rẹ mulẹ pe laipẹ laijinna, oun ati iyawo oun yoo tun tun yigi so, ti idile oun yoo si pada duro re. Saaju la ti mu wa fun yin pe Abdul Wasiu ti sọ fun ileeṣẹ BBC Yoruba pe ni nibayi, ija ti pari laarin oun ati iyawo rẹ. ''Inu mi dun pupọ. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun ati awọn ọmọ Naijiria fun aduroti wọn'' O ṣalaye pe lọdọ Risikatu loun ti kuro laarọ yii ati pe ko ni pẹ ti awọn yoo fi tun ṣe yigi pada'' Laipẹ yii ni awọn eeyan n beere boya awọn mejeeji yoo pari ija laarin ara wọn. Koda iyawo Gomina ipinlẹ Kwara sọ wipe, oun yoo gbiyanju lati pari ija laarin awọn mejeeji. Ninu ohun ta ri gbọ lẹnu Baba Kaosara bakan naa o sọ pe, iyawo Gomina lo ba awọn pari ija naa ,ti o si tun ṣatọkun bi wọn ti ṣe jijọ ya aworan papọ. Nigba ti BBC Yoruba bi Abdulwasiu pe ki ni yoo sẹlẹ lẹyin ti wọn ba tun yigi se, ti aya rẹ si tun bi ọmọ oloju bulu, baba Kaosara dahun pe ọmọ oloju gan ni oun n tọrọ lọwọ Ọlọrun bayii. "Inu mi yoo dun pupọ ta ba tun bi ọmọ ti oju rẹ yoo bulu, koda, ki ni mo fẹ fi ọmọ olju funfun se mọ, mo tiẹ n gbadura pe gbogbo ọmọ ti Ọlọrun yoo ba fun mi siwaju, ki wọn jẹ oloju bulu." Abdulwasiu ti wa kesi awọn ọmọ Naijiria lati ṣe iranwọ fun ohun ni[pa ọna iṣẹ lati le fi tọju mọlẹbi rẹ. O sọ pe ko si iṣẹ kankan lọwọ oun bayii, toun si n beere iranwọ lọdọ awọn araalu lati se atọna bi oun yoo se ri isẹ.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-53847428
2health
The New Pandemic: Kíni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ń sọ nípa rẹ̀?
Ẹ gbé owó silẹ̀ fún àwọn iṣẹ iwadii lori wọn ki wọn to tun maa gbẹbọ lọwọ agbaye- Awon onimọ sayẹnsi Sars, Swine Flu, Spanish Flu, MErs, Ebola ati Coronavirus jẹ diẹ lara awọn ajakalé arun to ti mu ẹmi ọpọ eniyan lọ ni gbogob agbaye sẹyin. Bayii, ọpọlọpọ orilẹ-ede ni ko tii bọ lọwọ iṣoro ajakalẹ arun coronavirus titi di asiko yii. Sugbọn awọn onimó sayẹnsi ni agbaye tun ti n pariwo ajakalẹ arun miran ti wọn ni o m bọ lọna ti o ṣeeṣe ko di nla ni agbaye. Orilẹ-ede China ni wọn tun ti ni yoo ti fẹẹ jade. Wọn ni ajakalé arun naa ko tii lewu lasiko yii ṣugbọn ẹfọn, ayipada oju ọjọ ati ooru lee sọo di nla mọ agbaye lọwọ. Awọn onimọ sayẹnsi parọwa pe ki awọn eeyan gbe owo silẹ fun iṣẹ iwadii ki ajakalẹ arun naa to di nkan miran ni agbaye,
The New Pandemic: Kíni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ń sọ nípa rẹ̀? Ẹ gbé owó silẹ̀ fún àwọn iṣẹ iwadii lori wọn ki wọn to tun maa gbẹbọ lọwọ agbaye- Awon onimọ sayẹnsi Sars, Swine Flu, Spanish Flu, MErs, Ebola ati Coronavirus jẹ diẹ lara awọn ajakalé arun to ti mu ẹmi ọpọ eniyan lọ ni gbogob agbaye sẹyin. Bayii, ọpọlọpọ orilẹ-ede ni ko tii bọ lọwọ iṣoro ajakalẹ arun coronavirus titi di asiko yii. Sugbọn awọn onimó sayẹnsi ni agbaye tun ti n pariwo ajakalẹ arun miran ti wọn ni o m bọ lọna ti o ṣeeṣe ko di nla ni agbaye. Orilẹ-ede China ni wọn tun ti ni yoo ti fẹẹ jade. Wọn ni ajakalé arun naa ko tii lewu lasiko yii ṣugbọn ẹfọn, ayipada oju ọjọ ati ooru lee sọo di nla mọ agbaye lọwọ. Awọn onimọ sayẹnsi parọwa pe ki awọn eeyan gbe owo silẹ fun iṣẹ iwadii ki ajakalẹ arun naa to di nkan miran ni agbaye,
https://www.bbc.com/yoruba/55033372
1entertainment
Nollywood In Court: Baba Ijesa, Baba Suwe, Yetunde Wunmi àtàwọn òṣèré tíátà tó ṣe ẹjọ́
Pupọ ninu awọn gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, ti ọpọlọpọ alatilẹyin ati awọn ololufẹ wọn kaakiri agbaye ni ifẹ si, ti wọn si ni ibọwọ fun amọ ti ọrọ ile ẹjọ n gbe wọn saye lakoko yii. Ọpọlọpọ igba ni awọn gbajugbaja naa ti ja awọn ọlọlufẹ wọn kulẹ latari awọn iwa ti ko daa ti wọn hu, ti o si ran ọpọlọpọ laarin wọn si ẹwọn lati lọ jẹ iya ẹṣẹ wọn. BBC Yoruba ṣe akojọpọ awọn gbajugbaja oṣere tiata ni orilẹede Naijiria ti wọn ti ṣagbako ẹwọn tabi ri ogun ile ẹjo nitori iwa ibajẹ ti wọn hu. Baba Ijesha: Ile-ẹjọ kan ni Ikeja ran gbajugbaja oṣere Olanrewaju James Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha, lọ si ẹwọn ọdun marun un leyin ti ile ẹjo kede pe o jẹbí esun ifipa banilopọ to ṣe si ọmọ ọdun merinla kan. Adajọ Oluwatoyin Taiwo da Baba Ijesha lẹbi fun iwa aiṣedede si ọmọ kan, ilọkulọ ibalopọ, ati igbiyanju ifipabanilopọ. Gbajugbaja oṣere Yoruba ti o ti di oloogbe, Babatunde Omidina, ti ọpọ mọ si Baba Suwe ni ọwọ ajọ NDLEA tẹ ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin, ti wọn si fi ẹsun pe o gbe ogun oloro kuro lorilẹede Naijiria. Baba Suwe lo ọpọlọpọ oṣe ni ahamọ ki ile ẹjo to wa pada daa lare pe ko jẹbi ẹsun ti ajọ naa fi kan an. Taiwo Akinwande (Wunmi) Lọdun 2007, gbajugbaja oṣere obinrin oni tiata, Taiwo Akinwade ti ọpọ mọ si Wummi, ni ile ẹjo ran lọ si ẹwọn ọdun mẹta lẹyin ti ile ẹjọ kede pe o jẹ bi ẹsun gbigbe ogun oloro. Ni papakọ ofurufu, Murtala Muhammed ni ọwọ ajọ NDLEA ti tẹ gbajugaja osere tiata naa nigba ti o fẹ gbera lọ si ilu London. O to oogun oloro mejilelaadọrun ti ajọ NDLEA ba lara arabinrin Taiwo Akinwade nigba naa. Gbagbajugba osere tiata, Bimbo Akinsanya ni o ri ogun ile ejọ latari bi wọn ṣe fi ẹsun ipaniyan kan an. Gbajugbaja osere Bukola Babalola, 'Bukky Black' ni wọn fi ẹsun ipaniyan kan pe o ṣeku pa ọmọ onilẹ kan ni agbegbe Ikorodu ni ipinlẹ Eko. Babalola ni wọn gbe lo si ile ẹjọ ti o si lo ọpọlọpọ ọsẹ ni atimolẹ. Oṣerebinrin yii ko fibẹ foju han mọ ninu awọn fiimu ati pe ko gbe ni orilẹede Naijrira mọ. Tayo Odueke(Sikiratu Sindodo) Tayo Odueke jẹ gbajugbaja osere tiata ti ọpọ mọ si Sikiratu Sidondo, ni ọdun diẹ sẹyin ni wọn fi ẹsun iṣekupa ọmọdekunrin kan kan an. Ẹni ọdun kan ati oṣu mẹrin ni ọmọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Daramola ni agbegbe Adeniyi Jones ni ipinlẹ Eko. Ọwọ olopaa tẹ oṣere ọhun, o si lo ọpọlọpọ ọsẹ ni agọ wọn, ki awọn molẹbi ọmọ to ni awọn o ṣe ẹjọ mọ ati pe ko jẹbi ẹsun naa. Gbajugbaja oṣere fiimu ni ede Gẹẹsi, Ibinabo Fiberesima, pẹlu awọn to lọ si ẹwọn lẹyin ti o fi ọkọ ayokẹlẹ rẹ ṣeku pa Dokita Giwa Suraj latari bi o ṣe wa ọkọ naa ni iwakuwa. Ile ẹjo giga ipinlẹ Eko wa ran ọmọbirin oṣere tiata naa lọ si ẹwọn ọdun marun un. Ṣugbọn, ile ẹjo da gbajugbaja oṢere tiata naa sile lẹyin ti o san owo to to milọnu meji naira. Babalola Falemi, olorin ti ọpọ mọ si Sauce Kid ni ọwọ Ọlọpaa tẹ lorilẹede Amẹrika fun ẹsun ole jija, ti o si ri ẹwọn ọdun meji he. Iroyin sọ pe olorin naa ji kaadi banki mẹẹdogun, ti o si parọ 'PIN' wọn lati fi igba owo lẹnu ẹrọ 'ATM.' Sauce Kid ji owo to to ẹgbẹrun mẹẹdọgun owo dọla. Ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha forí sánpọ́n, agbẹjọ́rò rẹ̀ kò yọjú sílé ẹjọ́
Nollywood In Court: Baba Ijesa, Baba Suwe, Yetunde Wunmi àtàwọn òṣèré tíátà tó ṣe ẹjọ́ Pupọ ninu awọn gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, ti ọpọlọpọ alatilẹyin ati awọn ololufẹ wọn kaakiri agbaye ni ifẹ si, ti wọn si ni ibọwọ fun amọ ti ọrọ ile ẹjọ n gbe wọn saye lakoko yii. Ọpọlọpọ igba ni awọn gbajugbaja naa ti ja awọn ọlọlufẹ wọn kulẹ latari awọn iwa ti ko daa ti wọn hu, ti o si ran ọpọlọpọ laarin wọn si ẹwọn lati lọ jẹ iya ẹṣẹ wọn. BBC Yoruba ṣe akojọpọ awọn gbajugbaja oṣere tiata ni orilẹede Naijiria ti wọn ti ṣagbako ẹwọn tabi ri ogun ile ẹjo nitori iwa ibajẹ ti wọn hu. Baba Ijesha: Ile-ẹjọ kan ni Ikeja ran gbajugbaja oṣere Olanrewaju James Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha, lọ si ẹwọn ọdun marun un leyin ti ile ẹjo kede pe o jẹbí esun ifipa banilopọ to ṣe si ọmọ ọdun merinla kan. Adajọ Oluwatoyin Taiwo da Baba Ijesha lẹbi fun iwa aiṣedede si ọmọ kan, ilọkulọ ibalopọ, ati igbiyanju ifipabanilopọ. Gbajugbaja oṣere Yoruba ti o ti di oloogbe, Babatunde Omidina, ti ọpọ mọ si Baba Suwe ni ọwọ ajọ NDLEA tẹ ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin, ti wọn si fi ẹsun pe o gbe ogun oloro kuro lorilẹede Naijiria. Baba Suwe lo ọpọlọpọ oṣe ni ahamọ ki ile ẹjo to wa pada daa lare pe ko jẹbi ẹsun ti ajọ naa fi kan an. Taiwo Akinwande (Wunmi) Lọdun 2007, gbajugbaja oṣere obinrin oni tiata, Taiwo Akinwade ti ọpọ mọ si Wummi, ni ile ẹjo ran lọ si ẹwọn ọdun mẹta lẹyin ti ile ẹjọ kede pe o jẹ bi ẹsun gbigbe ogun oloro. Ni papakọ ofurufu, Murtala Muhammed ni ọwọ ajọ NDLEA ti tẹ gbajugaja osere tiata naa nigba ti o fẹ gbera lọ si ilu London. O to oogun oloro mejilelaadọrun ti ajọ NDLEA ba lara arabinrin Taiwo Akinwade nigba naa. Gbagbajugba osere tiata, Bimbo Akinsanya ni o ri ogun ile ejọ latari bi wọn ṣe fi ẹsun ipaniyan kan an. Gbajugbaja osere Bukola Babalola, 'Bukky Black' ni wọn fi ẹsun ipaniyan kan pe o ṣeku pa ọmọ onilẹ kan ni agbegbe Ikorodu ni ipinlẹ Eko. Babalola ni wọn gbe lo si ile ẹjọ ti o si lo ọpọlọpọ ọsẹ ni atimolẹ. Oṣerebinrin yii ko fibẹ foju han mọ ninu awọn fiimu ati pe ko gbe ni orilẹede Naijrira mọ. Tayo Odueke(Sikiratu Sindodo) Tayo Odueke jẹ gbajugbaja osere tiata ti ọpọ mọ si Sikiratu Sidondo, ni ọdun diẹ sẹyin ni wọn fi ẹsun iṣekupa ọmọdekunrin kan kan an. Ẹni ọdun kan ati oṣu mẹrin ni ọmọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Daramola ni agbegbe Adeniyi Jones ni ipinlẹ Eko. Ọwọ olopaa tẹ oṣere ọhun, o si lo ọpọlọpọ ọsẹ ni agọ wọn, ki awọn molẹbi ọmọ to ni awọn o ṣe ẹjọ mọ ati pe ko jẹbi ẹsun naa. Gbajugbaja oṣere fiimu ni ede Gẹẹsi, Ibinabo Fiberesima, pẹlu awọn to lọ si ẹwọn lẹyin ti o fi ọkọ ayokẹlẹ rẹ ṣeku pa Dokita Giwa Suraj latari bi o ṣe wa ọkọ naa ni iwakuwa. Ile ẹjo giga ipinlẹ Eko wa ran ọmọbirin oṣere tiata naa lọ si ẹwọn ọdun marun un. Ṣugbọn, ile ẹjo da gbajugbaja oṢere tiata naa sile lẹyin ti o san owo to to milọnu meji naira. Babalola Falemi, olorin ti ọpọ mọ si Sauce Kid ni ọwọ Ọlọpaa tẹ lorilẹede Amẹrika fun ẹsun ole jija, ti o si ri ẹwọn ọdun meji he. Iroyin sọ pe olorin naa ji kaadi banki mẹẹdogun, ti o si parọ 'PIN' wọn lati fi igba owo lẹnu ẹrọ 'ATM.' Sauce Kid ji owo to to ẹgbẹrun mẹẹdọgun owo dọla. Ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha forí sánpọ́n, agbẹjọ́rò rẹ̀ kò yọjú sílé ẹjọ́
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-62190726
1entertainment
Hushpuppi: Kíni àwọn nkán tí kò hàn s'awọn èèyàn nípa arákùnrin tí ọlọ̀pàá Dubai fí ẹ̀sùn gbájúẹ̀ kàn?
Hushpuppi lorukọ ti ọpọ mọ si ti o si jẹ pe isọwọ fi ọla rẹ han sọ di ilumọọka loju opo ayelujara. Ṣugbọn ta ni arakunrin ti awọn ọlọpaa ilẹ Dubai ati ọtẹlẹmuyẹ Amẹrika gbe fun ẹsun gbajuẹ olowo iyebiyẹ yi? Nibo ni wọn ti bi,ta lawọn obi rẹ ati pe bawo lo ti se di ọlọrọ ti awọn eeyan kan n fi ọla rẹ tọrọ ki awọn naa ri bi tiẹ? Diẹ ree ninu nkan ti a ri ko jọ nipa Hushpuppi Ni pato ọjọ ti wọn bi Hushpuppi ti orukọ rẹ gangan n jẹ Ramoni ''Raymond'' Igbalode ko ye wa ṣugbọn bi a ba fi awọn nkan to sọ nipa ara rẹ wo ọrọ yi, ko le ti to ogoji ọdun. Eyi to sunmọ ootọ ni pe nilu Eko lo dagba si ki o to kuro lorileede Naijiria. Ninu awọn aworan rẹ nigba to wa ni kekere, a ri ibi to ti duro lara ọkọ nilu Eko ati awọn omiran to tọka si pe o ti gbe Naijiria daada ki o to lọ si ilu okere. Loju opo rẹ ni Instagram, o tun sọ nipa ọjọ ori rẹ pe oun ti gun oke agba bọ diẹ diẹ wọ ọmọ ọgbọn ọdun. Loṣu Kẹwa ọdun 2019 lo fi ọrọ yi sita eyi to jẹ ki a lero pe oṣu Kẹwa ni wọn bi. O ti ṣe awọn isẹ ọwọ kan ki o to kuro ni Naijiria ṣugbọn a ko ri aridaju lati fidi ọrọ mulẹ iru iṣẹ to jẹ. Lẹyin ti awọn ọlọpaa Dubai mu tan la bẹrẹ si ni ri aworan orisirisi to se afihan iru iṣẹ to kọkọ bẹrẹ si ni ṣe ki o to kuro ni Naijiria. Ọkan ninu iṣẹ ti wọn lo ṣe ni pe o jẹ olootu orin ti a mọ si Music Producer ti o si ba awọn olorin Naijiria kọọkan ṣiṣẹ pọ. Gẹgẹ bi awọn kan ti se sọ, wọn tun ni Ramoni ti ta aṣọ bọsikọrọ nigba to wa l'Eko koda wọn tun sọ wi pe o kọ isẹ foonu ati kọmputa tita ni Computer Village nilu Eko kan naa. Pẹlu gbogbo nkan ti a ka kalẹ yi, eleyi ti ohun gangan kii ye sọ nipa rẹ ni pe awọn obi rẹ kii se olowo ati pe ohun t'apata dide ni ki ẹlẹda to wa kọdi ọla si ọdọ ohun. Awọn mọlẹbi rẹ ko foju han lẹyin ti ọwọ tẹẹ Wọn ni ọwọ epo lọmọ araye n ba ni la, wọn kii ba ni la ọwọ ẹjẹ. Ṣaaju ki ọwọ to tẹ Hushpuppi, kii saba sọrọ nipa awọn mọlẹbi rẹ to bẹ loju opo ayelujara. Yatọ si aworan ko to fi sita nipa ọmọ iya rẹ obinrin to bimọ lọdun 2019 awọn eeyan ko le tọ ka si pe lagbaja tabi tamẹdun ni ọmọ iya Hushpuppi. Layajọ iya tabi Baba ti a ma si Father's Day ati Mother's Day, Hushpuppi kii kọ nkankannipa awọn obi rẹ debi ti awọn eeyan yoo fi le sọ pe bi awọn obi rẹ ti se ri ree tabi nibi ni wọn n gbe. Loju opo ẹni to pe ni ọmọ iya rẹ obinrin@ rawflesh_may_9 ko si nkankan nibẹ ni Instagram lati le fi tọka ẹni to n jẹ bẹ. Bi a ba sọ pe Hushpuppi nikan lo ri ara rẹ lasiko yi ati pe awọn mọlẹbi ko foju han pe eeyan awọn nii ṣe, a ko kuna rara lati sọ bẹ. Idahun si ibeere yi pin si ọna meji. Akọkọ ni pe ti a ba fi orukọ abinibi rẹ wo, tii se Ramoni, idile musulumi lo ṣeese ki o ti jade. Ninu awọn ọrọ kan to fi sioju opo Instagram rẹ, o sọ pe oore ti Allah ṣe fun ohun to ga ju lọ ni pe oun jẹ musulumi. Lọdun 2012 lo fi ọrọ yi sita ti a ko si le sọ boya o ṣi n ṣe ẹsin Islam titi di igba ti wọn fi mu. Bi a ba tibi orukọ rẹ to yi pada si Raymond wo, o ti le fi ẹsin Islam silẹ ṣugbọn o le jẹ inagijẹ lasan ni Raymond ki o ma se wi pe o pa ẹsin da. Bakan naa ninu fọnran fidio kan to fi si oju opo Instagram to ti n wẹ ninu omi iluwẹ igbalode, orin iyin ẹsin Kristẹni ni o n kọ ninu rẹ. Yatọ si eyi, pupọ awọn nkan to ma n kọ soju opo ayelujara, a ma fi adura to jọ ti Kristẹni sinu rẹ. Gbogbo awọn kan wọn yi ni ko jẹ ki a le sọ boya Kristẹni ni Hushpuppi tabi Musulumi. Eyi to daju ni pe ati ẹlẹsin Kristẹni ati ẹlẹsin musulumi lo wa ninu awọn eeyan to le ni miliọnu meji to n tẹle loju opo Instagram Wo bí ọwọ́ orílẹ̀-èdè Dubai ṣe tẹ Ramoni Igbalode tí gbogbo ayé ń pè ní Hushpuppi Ramoni Igbalode ti ọpọ eeyan mọ si Hushpuppi to fi orilẹ-ede Dubai ṣe ibujoko lasiko yii ni ọwọ awọn agbofinro ilẹ Dubai ti tẹ. Ninu fọnran fidio 'Fox Hunt 2' ni wọn ti ṣafihan rẹ. Lọjọbọ ni ileeṣẹ agbofinro dubai fi fidio bi wọn ṣe mu gbajugbaja ori ayelujara Instagram naa sita. Ọpọlọpọ owo bii owo to wa fun itọju Covid 19 ni Amẹrika ati awọn owo to le ni biliọnu dọla mẹrinlelogun ni wọn ti fi gbajuẹ gba. Ọlọpaa Dubai ṣalaye bi wọn ṣe mu Hushpuppi ninu atẹjade ti wọn fi sita ti BBC ri. Wọn ni awọn ti n fura sii ti pe pe o n ṣe awọn 'ọmọ Yahoo'ti wọn n gba awọn eeyan lori ayelujara. Nibẹ ni wọn ti fi si ori ikanni naa nipa Ramoni Igbalode ati Olalekan Jacb Ponle ti wọn n pe ni 'Woodberry'ati awọn ọmọ ilẹ Adulawọ miran. Iṣẹ akanṣẹ lati mu awọn ọmọ Yahoo ori ayelujara yii ni awọn agbofinro Dubai pe ni: 'Operation Fox Hunt 2' Awọn ẹṣẹ bii jiji owo ko lati asuwọn kan si ikeji, jiji owo lori ayelujara, wiwọ akata ayelujara ati eto inawo ẹlomiran lọna aitọ, ṣiṣẹ gbajuẹ fun awọn eeyan ni awujọ ati fun awọn banki ni wọn mu wọn fun. Ogagun Abdulla Khalifa Al Marri to n tukọ ileeṣẹ ọlọpaa gboriyin fun awọn ọlọpaa Dubai fun iṣẹ takuntakun ti wọn ti fi mu awọn mẹwaa naa. O ni eyi yoo tun din ole ori ayelujara ati gbajuẹ pẹlu ẹrọ ayarabiaṣa kọmputa ku diẹ lagbaye lasiko yii. Ki ni o ti kọkọ ṣẹlẹ lori mimu awọn Invictus àti Hushpuppi Invictus Obi, Hushpuppi, àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà méjì tí ẹ̀sùn gbájúẹ̀ wà lọ́rùn wọn Ajọ to n koju iwa jẹgudujẹra lorilẹede Naijiria, EFCC ti ni Ramoni Igbalode, alias Ray hushpuppy ni ẹjọ lati jẹ ni ọdọ wọn. EFCC to fi eyi lede loju opo ikansiraẹni Twitter wọn ni Hushpuppy is ẹni to gajulọ lorilẹede Naijiria ti wọn n wa bayii fun ẹsun iwa ọdaran lori ẹrọ ayelujara. Ọjọ kẹ̀wá, Osù Kẹfa ní wọn fí panpẹ́ ọba mú Hushpuppi ní United Arab Emirates lórí ẹ̀sùn lilọ gbajuẹ pẹlu ẹrọ ventilator to le ni $35million. Ajọ naa ni awọn mọ nipa jibiti owo ati 419 to ṣe ni Niajiria, ti awọn amugbalẹgbẹ rẹ si ti wa ni panpẹ awọn bayii lorilẹede Naijiria. EFCC fikun wi pe awọn n ṣiṣẹ pẹlu Ajọ Otẹlẹmuyẹ ilẹ Amerika, FBI titi ọwọ palaba rẹ fi segi.
Hushpuppi: Kíni àwọn nkán tí kò hàn s'awọn èèyàn nípa arákùnrin tí ọlọ̀pàá Dubai fí ẹ̀sùn gbájúẹ̀ kàn? Hushpuppi lorukọ ti ọpọ mọ si ti o si jẹ pe isọwọ fi ọla rẹ han sọ di ilumọọka loju opo ayelujara. Ṣugbọn ta ni arakunrin ti awọn ọlọpaa ilẹ Dubai ati ọtẹlẹmuyẹ Amẹrika gbe fun ẹsun gbajuẹ olowo iyebiyẹ yi? Nibo ni wọn ti bi,ta lawọn obi rẹ ati pe bawo lo ti se di ọlọrọ ti awọn eeyan kan n fi ọla rẹ tọrọ ki awọn naa ri bi tiẹ? Diẹ ree ninu nkan ti a ri ko jọ nipa Hushpuppi Ni pato ọjọ ti wọn bi Hushpuppi ti orukọ rẹ gangan n jẹ Ramoni ''Raymond'' Igbalode ko ye wa ṣugbọn bi a ba fi awọn nkan to sọ nipa ara rẹ wo ọrọ yi, ko le ti to ogoji ọdun. Eyi to sunmọ ootọ ni pe nilu Eko lo dagba si ki o to kuro lorileede Naijiria. Ninu awọn aworan rẹ nigba to wa ni kekere, a ri ibi to ti duro lara ọkọ nilu Eko ati awọn omiran to tọka si pe o ti gbe Naijiria daada ki o to lọ si ilu okere. Loju opo rẹ ni Instagram, o tun sọ nipa ọjọ ori rẹ pe oun ti gun oke agba bọ diẹ diẹ wọ ọmọ ọgbọn ọdun. Loṣu Kẹwa ọdun 2019 lo fi ọrọ yi sita eyi to jẹ ki a lero pe oṣu Kẹwa ni wọn bi. O ti ṣe awọn isẹ ọwọ kan ki o to kuro ni Naijiria ṣugbọn a ko ri aridaju lati fidi ọrọ mulẹ iru iṣẹ to jẹ. Lẹyin ti awọn ọlọpaa Dubai mu tan la bẹrẹ si ni ri aworan orisirisi to se afihan iru iṣẹ to kọkọ bẹrẹ si ni ṣe ki o to kuro ni Naijiria. Ọkan ninu iṣẹ ti wọn lo ṣe ni pe o jẹ olootu orin ti a mọ si Music Producer ti o si ba awọn olorin Naijiria kọọkan ṣiṣẹ pọ. Gẹgẹ bi awọn kan ti se sọ, wọn tun ni Ramoni ti ta aṣọ bọsikọrọ nigba to wa l'Eko koda wọn tun sọ wi pe o kọ isẹ foonu ati kọmputa tita ni Computer Village nilu Eko kan naa. Pẹlu gbogbo nkan ti a ka kalẹ yi, eleyi ti ohun gangan kii ye sọ nipa rẹ ni pe awọn obi rẹ kii se olowo ati pe ohun t'apata dide ni ki ẹlẹda to wa kọdi ọla si ọdọ ohun. Awọn mọlẹbi rẹ ko foju han lẹyin ti ọwọ tẹẹ Wọn ni ọwọ epo lọmọ araye n ba ni la, wọn kii ba ni la ọwọ ẹjẹ. Ṣaaju ki ọwọ to tẹ Hushpuppi, kii saba sọrọ nipa awọn mọlẹbi rẹ to bẹ loju opo ayelujara. Yatọ si aworan ko to fi sita nipa ọmọ iya rẹ obinrin to bimọ lọdun 2019 awọn eeyan ko le tọ ka si pe lagbaja tabi tamẹdun ni ọmọ iya Hushpuppi. Layajọ iya tabi Baba ti a ma si Father's Day ati Mother's Day, Hushpuppi kii kọ nkankannipa awọn obi rẹ debi ti awọn eeyan yoo fi le sọ pe bi awọn obi rẹ ti se ri ree tabi nibi ni wọn n gbe. Loju opo ẹni to pe ni ọmọ iya rẹ obinrin@ rawflesh_may_9 ko si nkankan nibẹ ni Instagram lati le fi tọka ẹni to n jẹ bẹ. Bi a ba sọ pe Hushpuppi nikan lo ri ara rẹ lasiko yi ati pe awọn mọlẹbi ko foju han pe eeyan awọn nii ṣe, a ko kuna rara lati sọ bẹ. Idahun si ibeere yi pin si ọna meji. Akọkọ ni pe ti a ba fi orukọ abinibi rẹ wo, tii se Ramoni, idile musulumi lo ṣeese ki o ti jade. Ninu awọn ọrọ kan to fi sioju opo Instagram rẹ, o sọ pe oore ti Allah ṣe fun ohun to ga ju lọ ni pe oun jẹ musulumi. Lọdun 2012 lo fi ọrọ yi sita ti a ko si le sọ boya o ṣi n ṣe ẹsin Islam titi di igba ti wọn fi mu. Bi a ba tibi orukọ rẹ to yi pada si Raymond wo, o ti le fi ẹsin Islam silẹ ṣugbọn o le jẹ inagijẹ lasan ni Raymond ki o ma se wi pe o pa ẹsin da. Bakan naa ninu fọnran fidio kan to fi si oju opo Instagram to ti n wẹ ninu omi iluwẹ igbalode, orin iyin ẹsin Kristẹni ni o n kọ ninu rẹ. Yatọ si eyi, pupọ awọn nkan to ma n kọ soju opo ayelujara, a ma fi adura to jọ ti Kristẹni sinu rẹ. Gbogbo awọn kan wọn yi ni ko jẹ ki a le sọ boya Kristẹni ni Hushpuppi tabi Musulumi. Eyi to daju ni pe ati ẹlẹsin Kristẹni ati ẹlẹsin musulumi lo wa ninu awọn eeyan to le ni miliọnu meji to n tẹle loju opo Instagram Wo bí ọwọ́ orílẹ̀-èdè Dubai ṣe tẹ Ramoni Igbalode tí gbogbo ayé ń pè ní Hushpuppi Ramoni Igbalode ti ọpọ eeyan mọ si Hushpuppi to fi orilẹ-ede Dubai ṣe ibujoko lasiko yii ni ọwọ awọn agbofinro ilẹ Dubai ti tẹ. Ninu fọnran fidio 'Fox Hunt 2' ni wọn ti ṣafihan rẹ. Lọjọbọ ni ileeṣẹ agbofinro dubai fi fidio bi wọn ṣe mu gbajugbaja ori ayelujara Instagram naa sita. Ọpọlọpọ owo bii owo to wa fun itọju Covid 19 ni Amẹrika ati awọn owo to le ni biliọnu dọla mẹrinlelogun ni wọn ti fi gbajuẹ gba. Ọlọpaa Dubai ṣalaye bi wọn ṣe mu Hushpuppi ninu atẹjade ti wọn fi sita ti BBC ri. Wọn ni awọn ti n fura sii ti pe pe o n ṣe awọn 'ọmọ Yahoo'ti wọn n gba awọn eeyan lori ayelujara. Nibẹ ni wọn ti fi si ori ikanni naa nipa Ramoni Igbalode ati Olalekan Jacb Ponle ti wọn n pe ni 'Woodberry'ati awọn ọmọ ilẹ Adulawọ miran. Iṣẹ akanṣẹ lati mu awọn ọmọ Yahoo ori ayelujara yii ni awọn agbofinro Dubai pe ni: 'Operation Fox Hunt 2' Awọn ẹṣẹ bii jiji owo ko lati asuwọn kan si ikeji, jiji owo lori ayelujara, wiwọ akata ayelujara ati eto inawo ẹlomiran lọna aitọ, ṣiṣẹ gbajuẹ fun awọn eeyan ni awujọ ati fun awọn banki ni wọn mu wọn fun. Ogagun Abdulla Khalifa Al Marri to n tukọ ileeṣẹ ọlọpaa gboriyin fun awọn ọlọpaa Dubai fun iṣẹ takuntakun ti wọn ti fi mu awọn mẹwaa naa. O ni eyi yoo tun din ole ori ayelujara ati gbajuẹ pẹlu ẹrọ ayarabiaṣa kọmputa ku diẹ lagbaye lasiko yii. Ki ni o ti kọkọ ṣẹlẹ lori mimu awọn Invictus àti Hushpuppi Invictus Obi, Hushpuppi, àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà méjì tí ẹ̀sùn gbájúẹ̀ wà lọ́rùn wọn Ajọ to n koju iwa jẹgudujẹra lorilẹede Naijiria, EFCC ti ni Ramoni Igbalode, alias Ray hushpuppy ni ẹjọ lati jẹ ni ọdọ wọn. EFCC to fi eyi lede loju opo ikansiraẹni Twitter wọn ni Hushpuppy is ẹni to gajulọ lorilẹede Naijiria ti wọn n wa bayii fun ẹsun iwa ọdaran lori ẹrọ ayelujara. Ọjọ kẹ̀wá, Osù Kẹfa ní wọn fí panpẹ́ ọba mú Hushpuppi ní United Arab Emirates lórí ẹ̀sùn lilọ gbajuẹ pẹlu ẹrọ ventilator to le ni $35million. Ajọ naa ni awọn mọ nipa jibiti owo ati 419 to ṣe ni Niajiria, ti awọn amugbalẹgbẹ rẹ si ti wa ni panpẹ awọn bayii lorilẹede Naijiria. EFCC fikun wi pe awọn n ṣiṣẹ pẹlu Ajọ Otẹlẹmuyẹ ilẹ Amerika, FBI titi ọwọ palaba rẹ fi segi.
https://www.bbc.com/yoruba/afrika-53104083
1entertainment
Megabite: Ilé-ìwé ni mo ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ
Moruf Bello, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Megabite, ti gba àwọn òbí ní ìmọ̀ràn pé kí wọn máse dí ọmọ wọn lọ́wọ́, tó bá ní ẹ̀bùn kan. Lásìkò tó ń bá BBC Yòrùbá sọ̀rọ̀, Megabite ní ohunkohun tí òun bá rí ní àyíká òun, ni òun máa fi ń kọrin.
Megabite: Ilé-ìwé ni mo ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ Moruf Bello, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Megabite, ti gba àwọn òbí ní ìmọ̀ràn pé kí wọn máse dí ọmọ wọn lọ́wọ́, tó bá ní ẹ̀bùn kan. Lásìkò tó ń bá BBC Yòrùbá sọ̀rọ̀, Megabite ní ohunkohun tí òun bá rí ní àyíká òun, ni òun máa fi ń kọrin.
https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-43448290
3politics
Ṣé lóòótọ́ ní pé àjọ elétò ìdìbò INEC láwọn ibùdó ìforúkọsílẹ̀ olùdìbò ti wọ́n yà sọtọ ní Niger Republic?
Lawọn oju opo kaakiri ni Naijiria oriṣi iroyin la n foju ri ni paapa bayi ti akoko idibo ti n sunmọ ni Naijiria. Pupọ awọn iroyin yi ni ko fi gbogbo ara sunmọ ootọ tawọn miran si jẹ agbelẹro patapata. Ninu iwadii taa maa n ṣe labẹ ẹka to n tan imọlẹ si ayederu iroyin BBC, a ṣawari iroyin kan to sọ pe ajọ eleto idibo Naijiria INEC ti ya awọn ibudo idibo kan sọtọ lorileede Niger. Se lootọ ni iroyin yi abi ahesọ ni? Ohun ti iwadii wa ṣe afihan ree Akọroyin wa to kan si ajọ eleto idibo INEC sọ pe ajọ naa ni awọn ko ni aaye iforukọsilẹ kankan ni orileede Niger bawọn iroyin ẹlẹjẹ to gbode loju opo ayelujara ṣe n wi. Ọkan ninu awọn iroyin taa n wi leleyi ti Nche Nwabunkiek kanfi sita to ti sọ pe ajọ INEC ni aaye idibo to le ni ogun lorileede Niger. Nwabunike kọ ọrọ rẹ yi sabẹ eleyi ti ileeṣẹ iroyin oju opo ayelujara Sahara Reporters fi sita. Ọrọ yi lawọn eeyan ri ti wọn si ya sọtọ ki wọn to bẹrẹ si ni pin kaakiri oju opo ayelujara ni paapa oju opo Whatsapp. Iwadii lati ọwọ ẹka BBC to n risi itanmọlẹ si iroyin ẹlẹjẹ BBC Disinformation fi han pe oju opo Nwabunike to wa ni Facebbok gbarọgudu opo ni. Iwadii fi han pe eeyan mẹsan lo ni gẹgẹ bi ọrẹ́ọ ati ko si ni iroyin kankan to ṣafihan pe eeyan gidi to lorukọ lo ni oju opo naa. Ni ṣoki, oju opo ti wọ́n da kalẹ ti ko ni okun lọrun taa n pe ni bot account ni oju opo rẹ yi jẹ. Lọpọ igba iru awọn oju opo yi ni wọn maa fi n tan iroyin ayederu kaakiri gẹgẹ bi iwadii wa lọdọ INEC ṣe fihan. Ọrọ ti oju opo Nwabunike gbe sita yi di nkan tawọn mii tẹwọ gba. Koda awọn mii tun fi kun ọrọ naa lati le jẹ ki o di itẹwọgba. Arakunrin kan loju opo Facebook, Mazi IK Ijezie jẹ ọkan ninu wọn. Ohun to ṣe ni pe o fi aworan awọn eeyan kan kun ọrọ yi to si ni wọn to lati gba kaadi idibo ọlọjọ pipẹ ni ọkan ninu awọn aaye iforukọsilẹ to wa ni Niger. Iwadii wa fihan pe aworan to pe ni ti Niger yi ti n tan kaakiri oju opo ayelujara lati oṣu Keje ọdun 2018 ati pe nibi idibo Gomina ipinlẹ Ekiti ni wọn ti ya aworan yi. Agbẹnusọ INEC Festus Okoye sọ fun BBC pe ofin ko faaye gba awọn lati forukọ awọn oludibo kankan silẹ lẹyin odi ibi ti ilẹ Naijiria de tori naa ko si bawọn ṣe le lọ ṣeto iforukọsilẹ fawọn eeyan ni Niger. O ni bi eeyan kankan ba forukọsilẹ loju opo INEC o di dandan ki iru eeyan bẹẹ foju han ni aaye ti wọn yoo ti ya aworan rẹ silẹ ti wọn ba fẹ dibo ni ibudo idibo. Ajọ eleto idibo INEC fi kun pe awọn ni ibudo idibo to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan (176, 846) ni orileede Naijiria awọn ko si ni ibudo idibo kankan lẹyin odi. Arakunrin Okoye fi kun pe ọrọ yi wa lara awọn ahesọ ọrọ tawọn kan n gbe kaakiri lati fi mu iyapa ati ija ẹlẹyamẹya wa laarin awọn eeyan Naijiria. Lẹnu ọjọ mẹta yi, wahala ati ri kaadi idibo ọlọjọ pipẹ gba ni Naijiria da bi nkan. Ko pe si asiko yi lawọn kan sọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo n kọdi awọn ẹya kan lorileede Naijiria lati ri kaadi idibo yi gba ni ilu Eko. Gbogbo bi awọn eeyan ṣe n ṣuuru bo ibudo iforukọsilẹyi lo mu ki ajọ INEC kede pe awọn yoo sunjọ gbedeke gbigba kaadi idibo yi siwaju si.
Ṣé lóòótọ́ ní pé àjọ elétò ìdìbò INEC láwọn ibùdó ìforúkọsílẹ̀ olùdìbò ti wọ́n yà sọtọ ní Niger Republic? Lawọn oju opo kaakiri ni Naijiria oriṣi iroyin la n foju ri ni paapa bayi ti akoko idibo ti n sunmọ ni Naijiria. Pupọ awọn iroyin yi ni ko fi gbogbo ara sunmọ ootọ tawọn miran si jẹ agbelẹro patapata. Ninu iwadii taa maa n ṣe labẹ ẹka to n tan imọlẹ si ayederu iroyin BBC, a ṣawari iroyin kan to sọ pe ajọ eleto idibo Naijiria INEC ti ya awọn ibudo idibo kan sọtọ lorileede Niger. Se lootọ ni iroyin yi abi ahesọ ni? Ohun ti iwadii wa ṣe afihan ree Akọroyin wa to kan si ajọ eleto idibo INEC sọ pe ajọ naa ni awọn ko ni aaye iforukọsilẹ kankan ni orileede Niger bawọn iroyin ẹlẹjẹ to gbode loju opo ayelujara ṣe n wi. Ọkan ninu awọn iroyin taa n wi leleyi ti Nche Nwabunkiek kanfi sita to ti sọ pe ajọ INEC ni aaye idibo to le ni ogun lorileede Niger. Nwabunike kọ ọrọ rẹ yi sabẹ eleyi ti ileeṣẹ iroyin oju opo ayelujara Sahara Reporters fi sita. Ọrọ yi lawọn eeyan ri ti wọn si ya sọtọ ki wọn to bẹrẹ si ni pin kaakiri oju opo ayelujara ni paapa oju opo Whatsapp. Iwadii lati ọwọ ẹka BBC to n risi itanmọlẹ si iroyin ẹlẹjẹ BBC Disinformation fi han pe oju opo Nwabunike to wa ni Facebbok gbarọgudu opo ni. Iwadii fi han pe eeyan mẹsan lo ni gẹgẹ bi ọrẹ́ọ ati ko si ni iroyin kankan to ṣafihan pe eeyan gidi to lorukọ lo ni oju opo naa. Ni ṣoki, oju opo ti wọ́n da kalẹ ti ko ni okun lọrun taa n pe ni bot account ni oju opo rẹ yi jẹ. Lọpọ igba iru awọn oju opo yi ni wọn maa fi n tan iroyin ayederu kaakiri gẹgẹ bi iwadii wa lọdọ INEC ṣe fihan. Ọrọ ti oju opo Nwabunike gbe sita yi di nkan tawọn mii tẹwọ gba. Koda awọn mii tun fi kun ọrọ naa lati le jẹ ki o di itẹwọgba. Arakunrin kan loju opo Facebook, Mazi IK Ijezie jẹ ọkan ninu wọn. Ohun to ṣe ni pe o fi aworan awọn eeyan kan kun ọrọ yi to si ni wọn to lati gba kaadi idibo ọlọjọ pipẹ ni ọkan ninu awọn aaye iforukọsilẹ to wa ni Niger. Iwadii wa fihan pe aworan to pe ni ti Niger yi ti n tan kaakiri oju opo ayelujara lati oṣu Keje ọdun 2018 ati pe nibi idibo Gomina ipinlẹ Ekiti ni wọn ti ya aworan yi. Agbẹnusọ INEC Festus Okoye sọ fun BBC pe ofin ko faaye gba awọn lati forukọ awọn oludibo kankan silẹ lẹyin odi ibi ti ilẹ Naijiria de tori naa ko si bawọn ṣe le lọ ṣeto iforukọsilẹ fawọn eeyan ni Niger. O ni bi eeyan kankan ba forukọsilẹ loju opo INEC o di dandan ki iru eeyan bẹẹ foju han ni aaye ti wọn yoo ti ya aworan rẹ silẹ ti wọn ba fẹ dibo ni ibudo idibo. Ajọ eleto idibo INEC fi kun pe awọn ni ibudo idibo to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan (176, 846) ni orileede Naijiria awọn ko si ni ibudo idibo kankan lẹyin odi. Arakunrin Okoye fi kun pe ọrọ yi wa lara awọn ahesọ ọrọ tawọn kan n gbe kaakiri lati fi mu iyapa ati ija ẹlẹyamẹya wa laarin awọn eeyan Naijiria. Lẹnu ọjọ mẹta yi, wahala ati ri kaadi idibo ọlọjọ pipẹ gba ni Naijiria da bi nkan. Ko pe si asiko yi lawọn kan sọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo n kọdi awọn ẹya kan lorileede Naijiria lati ri kaadi idibo yi gba ni ilu Eko. Gbogbo bi awọn eeyan ṣe n ṣuuru bo ibudo iforukọsilẹyi lo mu ki ajọ INEC kede pe awọn yoo sunjọ gbedeke gbigba kaadi idibo yi siwaju si.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cv26nzlzegeo