labels
class label 5
classes | headline
stringlengths 38
163
| text
stringlengths 74
42.6k
| headline_text
stringlengths 142
42.7k
| url
stringlengths 35
53
|
---|---|---|---|---|
1entertainment
| Iyabo Ojo: Ìséde alẹ́ di àárọ̀ tí Sanwo-Olu ṣe kó bá ilé ìgbafẹ́ mi, gbèsè dé | Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Iyabo Ojo ti ke gbajare si ijọba ipinlẹ Eko lori igbele alẹ si aarọ to wa ni ipinlẹ naa. Igbele naa, tijọba gbe kalẹ lasiko igbele arun Coronavirus lati aago mejila oru si mẹrin aarọ, ni wn ko tii so rọ titi di akoko yii ni Eko. Iyabo Ojo ni ofin konile o gbele ni oru naa n pa oun lara, o ni gbese ti fẹ pa oun nitori igbele naa ti ṣe ipalara fun owo to yẹ ko wọle nile igbafẹ ti oun da silẹ. Oṣere naa lo fi ọrọ ọhun lede loju opo Instagram rẹ, nibi to ti bẹ gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ati igbakeji Aarẹ Naijiria, Yemi Osinbajo, pe ki wọn ka igbele naa kuro nilẹ. O ni "ibeere ti mo fẹ beere lọwọ ijọba ni pe, ki ni eredi gan ti ijọba ṣe paṣẹ igbele lati aago mejila oru si mẹrin idaji." Bo tilẹ jẹ pe o sọ pe oun mọ pe igbele naa wa lode nitori ajakalẹ arun Coronavirus to n ba gbogbo agbaye finra, ṣugbọn oun ko ri idi ti igbele yoo ṣe wa lode laarin oru ti ko si si lọsan gangan. Iyabo Ojo sọ pe "igbele yii ti n pa owo mi atawọn ẹlomiran to n ṣowo ile ijo ati ile igbafẹ lara." "Ṣe ọganjọ oru nikan ni arun Coronavirus maa n rin laarin ilu ni? Ṣebi awọn n lọ sinu ọja lọsan gangan." "Ẹyin ijọba, ẹ ni lati ṣalaye fun awa ara ilu idi ti ẹ ṣe fi igbele si aarin oru ti awọn kan maa ṣe owo ti wọn fi n bọ awọn mọlẹbi wọn." O ṣalaye pe awọn eeyan bi oun to ni ile igbafẹ ti ọpọ eeyan maa n ba dowo pọ loru, ni ofin konile-o-gbele naa pa lara julọ. Gbajumọ oṣere naa ni, "ko bojumu ki a da owo wa duro fun odidi ọdun kan gbako nitori Corona, nigba ti kii ṣe pe o ni owo kan pato ti ijọba n fun wa." "Gbogbo igba ti mo ba n lọ sile loru ni awọn ọlọpaa maa n da mi lọna pe igbele wa, ti wọn si maa n gba owo abẹtẹlẹ lọwọ mi." "Mo fẹ ki ijọba mọ pe mo ni awọn ọmọ, bẹẹ si ni mo ni awọn ẹbi ti mọ n bọ, ijọba ẹ ṣaanu wa o." "Mo n sọrọ lorukọ gbogbo awa ti a ni ile ijo ati igbafẹ ti igbele yii pa lara julọ nitori ijọba ko fun wa lowo kankan. Wọn sọ wa si igbele, bẹẹ si ni wọn tun maa n reti ki a maa san owo ori." Iyabo Ojo pari ọrọ rẹ pe, awọn ọlọpaa n fi akoko igbele naa mọọmọ gba owo ti ko tọ lọwọ awọn eeyan ilu loru ọganjọ ni. Lẹyin naa lo ke si ijọba lati ṣalaye pẹlu ẹri pe oru nikan ni arun Corona maa n rin tabi ki wọn ka igbele naa kuro nilẹ. | Iyabo Ojo: Ìséde alẹ́ di àárọ̀ tí Sanwo-Olu ṣe kó bá ilé ìgbafẹ́ mi, gbèsè dé Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Iyabo Ojo ti ke gbajare si ijọba ipinlẹ Eko lori igbele alẹ si aarọ to wa ni ipinlẹ naa. Igbele naa, tijọba gbe kalẹ lasiko igbele arun Coronavirus lati aago mejila oru si mẹrin aarọ, ni wn ko tii so rọ titi di akoko yii ni Eko. Iyabo Ojo ni ofin konile o gbele ni oru naa n pa oun lara, o ni gbese ti fẹ pa oun nitori igbele naa ti ṣe ipalara fun owo to yẹ ko wọle nile igbafẹ ti oun da silẹ. Oṣere naa lo fi ọrọ ọhun lede loju opo Instagram rẹ, nibi to ti bẹ gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ati igbakeji Aarẹ Naijiria, Yemi Osinbajo, pe ki wọn ka igbele naa kuro nilẹ. O ni "ibeere ti mo fẹ beere lọwọ ijọba ni pe, ki ni eredi gan ti ijọba ṣe paṣẹ igbele lati aago mejila oru si mẹrin idaji." Bo tilẹ jẹ pe o sọ pe oun mọ pe igbele naa wa lode nitori ajakalẹ arun Coronavirus to n ba gbogbo agbaye finra, ṣugbọn oun ko ri idi ti igbele yoo ṣe wa lode laarin oru ti ko si si lọsan gangan. Iyabo Ojo sọ pe "igbele yii ti n pa owo mi atawọn ẹlomiran to n ṣowo ile ijo ati ile igbafẹ lara." "Ṣe ọganjọ oru nikan ni arun Coronavirus maa n rin laarin ilu ni? Ṣebi awọn n lọ sinu ọja lọsan gangan." "Ẹyin ijọba, ẹ ni lati ṣalaye fun awa ara ilu idi ti ẹ ṣe fi igbele si aarin oru ti awọn kan maa ṣe owo ti wọn fi n bọ awọn mọlẹbi wọn." O ṣalaye pe awọn eeyan bi oun to ni ile igbafẹ ti ọpọ eeyan maa n ba dowo pọ loru, ni ofin konile-o-gbele naa pa lara julọ. Gbajumọ oṣere naa ni, "ko bojumu ki a da owo wa duro fun odidi ọdun kan gbako nitori Corona, nigba ti kii ṣe pe o ni owo kan pato ti ijọba n fun wa." "Gbogbo igba ti mo ba n lọ sile loru ni awọn ọlọpaa maa n da mi lọna pe igbele wa, ti wọn si maa n gba owo abẹtẹlẹ lọwọ mi." "Mo fẹ ki ijọba mọ pe mo ni awọn ọmọ, bẹẹ si ni mo ni awọn ẹbi ti mọ n bọ, ijọba ẹ ṣaanu wa o." "Mo n sọrọ lorukọ gbogbo awa ti a ni ile ijo ati igbafẹ ti igbele yii pa lara julọ nitori ijọba ko fun wa lowo kankan. Wọn sọ wa si igbele, bẹẹ si ni wọn tun maa n reti ki a maa san owo ori." Iyabo Ojo pari ọrọ rẹ pe, awọn ọlọpaa n fi akoko igbele naa mọọmọ gba owo ti ko tọ lọwọ awọn eeyan ilu loru ọganjọ ni. Lẹyin naa lo ke si ijọba lati ṣalaye pẹlu ẹri pe oru nikan ni arun Corona maa n rin tabi ki wọn ka igbele naa kuro nilẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/56789075 |
1entertainment
| Olutayo Amokade: 'Ẹ má boore Ọlọ́run mọ́ra; Ti mo bá ra ilé lọ́la màá gbé sórí ayélujára' | 'Ìjẹ̀bú tó ya wèrè gan an ni mí o' Gbajugbaja òṣeré Yollywood, Olutayọ Amọkade ti gbogbo ayé mọ̀ sí Ijẹbu rọ àwọn èèyàn láti ma bẹ̀rù idojukọ rara. O ni ipenija maa n sọ eeyan di ológo ni lọjọ ọ̀la. O ni: mo ti ṣiṣẹ ọjọ meje ri fún ọọdunrun naira péré (N300) nigba ti mo ṣi n ṣe generator man' iyẹn awọn oṣiṣẹ amunawa to n fa ina fun lilo ni òde eré. Kini ero Ijebu lori awọn oṣere to n ja lori ayelujara? Ijẹbu ni ọjà lasan ni àwọn oṣere Yollywood paapaa àwọn obinrin n fi ìjà lori ayelujara ṣe. O ni wón kan ń fi kun orukọ lasan ni. O gbà pe Ọlọrun lo ni ògo to maa n fun onikaluku nigba ti asiko ba yẹ. | Olutayo Amokade: 'Ẹ má boore Ọlọ́run mọ́ra; Ti mo bá ra ilé lọ́la màá gbé sórí ayélujára' 'Ìjẹ̀bú tó ya wèrè gan an ni mí o' Gbajugbaja òṣeré Yollywood, Olutayọ Amọkade ti gbogbo ayé mọ̀ sí Ijẹbu rọ àwọn èèyàn láti ma bẹ̀rù idojukọ rara. O ni ipenija maa n sọ eeyan di ológo ni lọjọ ọ̀la. O ni: mo ti ṣiṣẹ ọjọ meje ri fún ọọdunrun naira péré (N300) nigba ti mo ṣi n ṣe generator man' iyẹn awọn oṣiṣẹ amunawa to n fa ina fun lilo ni òde eré. Kini ero Ijebu lori awọn oṣere to n ja lori ayelujara? Ijẹbu ni ọjà lasan ni àwọn oṣere Yollywood paapaa àwọn obinrin n fi ìjà lori ayelujara ṣe. O ni wón kan ń fi kun orukọ lasan ni. O gbà pe Ọlọrun lo ni ògo to maa n fun onikaluku nigba ti asiko ba yẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/45352316 |
2health
| Coronavirus symptoms: Kí ni àwọn àpẹẹrẹ àrùn yìí, àti pé báwo ni mo ṣe leè dáàbò bo ara mi? | Arun Coronavirus ti tan de, o kere tan, ọgọrin orilẹ-ede, ilẹ Gẹẹsi ati Naijira si jẹ ọkan lara rẹ. Ṣugbọn kinni arun yii, ati pe bawo ni o ṣe n tan ka? Ọna to dara ju lati dabo bo ara ẹni ni lati maa fọ ọwọ ẹni, paapa pẹlu omi ati ọṣẹ. Arun Coronavirus ma n tan kan nigba ti ẹni to ba ti lugbadi arun naa ba wukọ, ti afẹfẹ si gbe. Ẹlomiran le mi iru afẹfẹ bẹ simu, tabi to ba fọwọ kan ibi (ori aga ijoko tabi ori tabili) ti arun naa ti bale, ti iru ẹni bẹ si fi ọwọ naa si oju, imu tabi ẹnu rẹ. Nitori naa, ki eeyan wukọ tabi sin sinu igbọnwọ, ṣiṣọra fun fifi ọwọ ti eeyan ko fọ kan oju ẹni, ati yiyẹba fun awọn to ni ti ni arun naa jẹ ọna kan pataki lati jina rere si arun ọhun. Awọn onimọ eto ilkera ti sọ pe Lilo iboju ko le fun eeyan ni abo to koju oṣuwọn lori arun naa. Ẹdọforo ẹni ni aruin Coronavirus ma n kọ lu, apẹrẹ arun ọhun si ma n bẹrẹ pẹlu iba, lẹyin rẹ ni ikọ, leyi to le yọri si isọro ati mi. Gẹgẹ bi awọn onimọ ijinlẹ ṣe sọ, apẹrẹ arun le bẹrẹ lati ẹyin ọjọ marun un ti eeyan ba ti lugbadi rẹ. Awọn to ba ti n fi apẹrẹ arun naa han lee ko ran elomiran ṣugbọn awọn ami kan ti fi han pe, awọn to ni arun ọhun le ko ran elomiran lai ṣe pe wọn ti bẹrẹ si n fi apẹrẹ rẹ han. Apẹrẹ arun ọhun le fara jọ aisan to wọn pọ bi otutu ati ọfinki, leyi to le ma mu ki eeyan tete fura pe Coronavirus lo n ba oun ja. Lọwọ yii, o jọ bi pe awọn to n jẹ Ọlọrun nipe nipasẹ arun naa kere jọjọ, bi ida kan si meji ninu ida ọgọrun. Ẹgbẹgbẹrun eeyan ni wọn ti n gba itọju lọwọ, ṣugbọn o ṣeṣe ki awọn naa jẹ Ọlọrun nipe, to tunọ si pe iye awọn to gbẹmi mi nitori arun naa le ga ju iwọn to wa nilẹ lọ, bakan naa, iye eeyan naa tun le lọ silẹ ju bi awọn onimọ ṣe lero lọ. Iwaadi ti ajọ eleto ilera agabye. WHO ṣe lara awọn eeyan ẹgbẹrundinlọgọta fi han pe: Awọn agbalagba ati awọn ti wọn ti ni aisan lara tẹlẹ (bii itọ ṣuga, aisan inu ọkan ati ikọ efee) le ṣaisan gidi. Itọju iru awọn bẹẹ si da le jijẹ ki wọn wa laaye titi ti ohun amuṣagbara ninu agọ ara wọn le fi le arun naa lọ. Ṣugbọn awọn eleto ilera ti n ṣeṣẹ lati ri ogun to le koju arun naa. Ajọ NHS ti sọ pe o ṣeṣe ki arun yii gbilẹ siwaju si nilẹ Gẹẹsi. Awọn ti wọn ba ni arun naa ni UK le pe ago NHS lori nọmba 111 fun igbani niyanju. Awọn to wa ni Naijiria ti wọn ba ri pe wọn ti ṣalabapade ẹni to ni arun ọhun lee pe nọmba 0800-970000-10 tabi 112. Oriṣiriṣi orilẹ-ede lo ti fi amọran lede fun awọn eeyan wọn lori awọn ohun ti wọn le ṣẹ ti wọn ba lugbadi arun naa tabi fara kan ẹni ti wọn funra si pe o ni arun ọhun. Ti o ba wa ni ilẹ Gẹẹsi ti o si nilo ayẹwo, mu diẹ lara itọ, igbẹ tabi ẹjẹ rẹ lọ sile iwosan fun ayẹwo naa. Ti o ba duro de esi ayẹwo rẹ, o dara ki o da wa ninu ile titi ti esi ayẹwo naa yoo fi de. Igbesẹ kan naa lo ni lati gbe to ba wa ni orilẹ-ede Naijiria. Bawo ni arun yii ṣe n tan kaakiri? Ọpọ awọn eeyan lo n fara kaasa arun yii kaakiri agabye, ṣugbọn ọpọ awọn mii to n ko arun naa ni awọn eleto ilera ko mọ nitori wọn ko fi to wọn leti. Lẹyin to bẹrẹ ni China, arun naa ti tan de South Korea, Italy, Iran atawọn ilẹ mii lagabye. | Coronavirus symptoms: Kí ni àwọn àpẹẹrẹ àrùn yìí, àti pé báwo ni mo ṣe leè dáàbò bo ara mi? Arun Coronavirus ti tan de, o kere tan, ọgọrin orilẹ-ede, ilẹ Gẹẹsi ati Naijira si jẹ ọkan lara rẹ. Ṣugbọn kinni arun yii, ati pe bawo ni o ṣe n tan ka? Ọna to dara ju lati dabo bo ara ẹni ni lati maa fọ ọwọ ẹni, paapa pẹlu omi ati ọṣẹ. Arun Coronavirus ma n tan kan nigba ti ẹni to ba ti lugbadi arun naa ba wukọ, ti afẹfẹ si gbe. Ẹlomiran le mi iru afẹfẹ bẹ simu, tabi to ba fọwọ kan ibi (ori aga ijoko tabi ori tabili) ti arun naa ti bale, ti iru ẹni bẹ si fi ọwọ naa si oju, imu tabi ẹnu rẹ. Nitori naa, ki eeyan wukọ tabi sin sinu igbọnwọ, ṣiṣọra fun fifi ọwọ ti eeyan ko fọ kan oju ẹni, ati yiyẹba fun awọn to ni ti ni arun naa jẹ ọna kan pataki lati jina rere si arun ọhun. Awọn onimọ eto ilkera ti sọ pe Lilo iboju ko le fun eeyan ni abo to koju oṣuwọn lori arun naa. Ẹdọforo ẹni ni aruin Coronavirus ma n kọ lu, apẹrẹ arun ọhun si ma n bẹrẹ pẹlu iba, lẹyin rẹ ni ikọ, leyi to le yọri si isọro ati mi. Gẹgẹ bi awọn onimọ ijinlẹ ṣe sọ, apẹrẹ arun le bẹrẹ lati ẹyin ọjọ marun un ti eeyan ba ti lugbadi rẹ. Awọn to ba ti n fi apẹrẹ arun naa han lee ko ran elomiran ṣugbọn awọn ami kan ti fi han pe, awọn to ni arun ọhun le ko ran elomiran lai ṣe pe wọn ti bẹrẹ si n fi apẹrẹ rẹ han. Apẹrẹ arun ọhun le fara jọ aisan to wọn pọ bi otutu ati ọfinki, leyi to le ma mu ki eeyan tete fura pe Coronavirus lo n ba oun ja. Lọwọ yii, o jọ bi pe awọn to n jẹ Ọlọrun nipe nipasẹ arun naa kere jọjọ, bi ida kan si meji ninu ida ọgọrun. Ẹgbẹgbẹrun eeyan ni wọn ti n gba itọju lọwọ, ṣugbọn o ṣeṣe ki awọn naa jẹ Ọlọrun nipe, to tunọ si pe iye awọn to gbẹmi mi nitori arun naa le ga ju iwọn to wa nilẹ lọ, bakan naa, iye eeyan naa tun le lọ silẹ ju bi awọn onimọ ṣe lero lọ. Iwaadi ti ajọ eleto ilera agabye. WHO ṣe lara awọn eeyan ẹgbẹrundinlọgọta fi han pe: Awọn agbalagba ati awọn ti wọn ti ni aisan lara tẹlẹ (bii itọ ṣuga, aisan inu ọkan ati ikọ efee) le ṣaisan gidi. Itọju iru awọn bẹẹ si da le jijẹ ki wọn wa laaye titi ti ohun amuṣagbara ninu agọ ara wọn le fi le arun naa lọ. Ṣugbọn awọn eleto ilera ti n ṣeṣẹ lati ri ogun to le koju arun naa. Ajọ NHS ti sọ pe o ṣeṣe ki arun yii gbilẹ siwaju si nilẹ Gẹẹsi. Awọn ti wọn ba ni arun naa ni UK le pe ago NHS lori nọmba 111 fun igbani niyanju. Awọn to wa ni Naijiria ti wọn ba ri pe wọn ti ṣalabapade ẹni to ni arun ọhun lee pe nọmba 0800-970000-10 tabi 112. Oriṣiriṣi orilẹ-ede lo ti fi amọran lede fun awọn eeyan wọn lori awọn ohun ti wọn le ṣẹ ti wọn ba lugbadi arun naa tabi fara kan ẹni ti wọn funra si pe o ni arun ọhun. Ti o ba wa ni ilẹ Gẹẹsi ti o si nilo ayẹwo, mu diẹ lara itọ, igbẹ tabi ẹjẹ rẹ lọ sile iwosan fun ayẹwo naa. Ti o ba duro de esi ayẹwo rẹ, o dara ki o da wa ninu ile titi ti esi ayẹwo naa yoo fi de. Igbesẹ kan naa lo ni lati gbe to ba wa ni orilẹ-ede Naijiria. Bawo ni arun yii ṣe n tan kaakiri? Ọpọ awọn eeyan lo n fara kaasa arun yii kaakiri agabye, ṣugbọn ọpọ awọn mii to n ko arun naa ni awọn eleto ilera ko mọ nitori wọn ko fi to wọn leti. Lẹyin to bẹrẹ ni China, arun naa ti tan de South Korea, Italy, Iran atawọn ilẹ mii lagabye. | https://www.bbc.com/yoruba/agbaye-51830260 |
5sports
| AFCON 2021 FINAL: Ta ni yoo gba ife ẹyẹ Afcon laarin Mane ati Salah? | Ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba jẹ eleyi ti ọpọ maa n foju sọna fun ninu idije Afcon to maa n waye nilẹ Afrika. Ti ọdun yii ko yatọ si tatẹyinwa. Koda oju awọn ololufẹ ere bọọlu n bẹ lọna nitori awọn ikọ meji to rapala de aṣekagba yii, ina piti ni wọn. Egypt ati Senegal ni yoo dijọ waako lọjọ Aiku lati mọ ẹni ti wọn yoo de lade Ọba ere bọọlu ni Afrika. Ni bayi, wọn ti gba ifẹsẹwọnsẹ mọkanlelaadọta ninu idije Afcon Cameroon 2021, ti papa iṣere Paul Biya to wa ni Olembe yoo si gbalejo asekagba naa. Ẹ jẹ ki a se agbeyẹwo awọn ikọ mejeeji ati iru aṣeyọri ti wọn ti ni ṣẹyin ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ yii. Odu ni Egypt nibi ka maa gba ife ẹyẹ Afcon: Ni meni meji, ba ba ni ka maa ka, Egypt ti gba ife ẹyẹ Afcon ni igba meje ọtọọtọ. Ninu akọsilẹ, ko si orileede miran ni Afrika to sunmọ wọn tabi to gba ife ẹyẹ yii ju wọn lọ. Ọdun 2010 ni wọn gba ife ẹyẹ naa kẹyin pẹlu bi wọn ti ṣe fagba han Black Stars Ghana pẹlu goolu kan sodo ninu aṣekagba. Ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba lati le fi kopa ninu idije Afcon, ta mọ si ''qualifiers'' ami ayo mejila ni wọn ko jọ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹfaa. Wọn lewaju isọri Keje lati le fi kopa ninu idije Afcon 2021. Nigba ti wọn de idije naa, Naijiria da wọn lagbo sina pẹlu goolu kan sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ isọri kẹrin. Ifidirẹmi yii dabi ẹni pe wọn ko ni tẹsiwaju ṣugbọn wọn gbọnra nu, ti wọn si gbiyanju titi ti wọn fi de aṣekagba. Senegal naa ko kẹrẹ, o ni atamátàsé ati adẹ̀yìnmú gidi: Orileede Senegal le ma gborukọ lori bi ti Egypt ṣugbọn awọn naa kii se aimọ lawujọ awọn orilẹede agbabọọlu ni Afrika. Ninu ifẹsẹwọnsẹ mejila ti wọn gba lera wọn, wọn ko fidi rẹmi ninu wọn. Wọn jawe olubori ninu mẹsan, wọn si gba ọmi ninu mẹta. Goolu mẹrinlelogun ni wọn ti jẹ lati oṣu Keje ọdun to kọja ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn kopa ninu rẹ, ti goolu mẹfa pere si wọle si awọn wọn. Bi a ba ni ka sọ nipa ikọ to ni atamatase ati awọn adẹyinmu ti ko kẹrẹ rara, Senegal jẹ ikọ to duro wamu wamu. Lọdun yii ohun to wa lọkan wọn ni bi wọn yoo se ṣaseyọri ninu aṣekagba. Lọdun 2002, Cameroon lo fidi wọn rẹmi ninu aṣekagba nipa pẹnariti, ti Algeria naa si gbewuro soju wọn ni Egypt pẹlu goolu kan sodo. Ninu irinajo wọn de aṣekagba lọdun yii, wọn ko jẹ goolu pupọ ni ipele kini ṣugbọn wọn tẹsiwajulati leke isọri keji. Igba ti wọn de abala komẹsẹoyọ ni wọn bẹrẹ si ni pitu. Goolu meji ni wọn fi da bantẹ iya fun Cape Verde lati ọwọ Sadio Mane ati Ahmadou Bamba Dieng. Equitorial Guinea naa gba igbaju ati igbamu lọwọ wọn pẹlu goolu mẹta sookan. Nigba ti Burkina Faso koju wọn ni abala to kangun si aṣekagba, goolu mẹta sookan lawọn naa fi gbara. Nkan to ku bayi ni ki wọn koju Egypt ni aṣekagba. Boya wọn yoo gba ife yẹ Afcon ni igba akọkọ ninu itan orileede wọn. Bo ti lẹ jẹ wi pe orileede meji ni yoo koju ara wọn, orukọ awọn agbabọọlu mejeeji yii, Sadio Mane ati Mo Salah lawọn eeyan n ran lẹnu. Idi ni pe awọn mejeeji jijọ n ṣe ọrọ aje pẹlu ẹgbẹ agbagbọọlu Liverpool nilẹ Gẹẹsi ni. Atamatase lawọn mejeeji, ti wọn si ti jijọ gba ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ ni Afrika. Ti Senegal yoo ba bori Egypt, Sadio Mane yoo ni ipa ribiribi lati ko nipa didoju ija kọ awọn adilemu Egypt. Amọ Salah naa ko ni gbẹni wa nitori pe oun naa yoo ja fita fita lati se bii ọkunrin. Ipade wa di ori papa nirọlẹ oni lati mọ irin ti yoo tẹ fun ekeji laarin ikọ Egypt ati Senegal, Sadio Mane ati Mo Salah, ẹ ku oju lọna. | AFCON 2021 FINAL: Ta ni yoo gba ife ẹyẹ Afcon laarin Mane ati Salah? Ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba jẹ eleyi ti ọpọ maa n foju sọna fun ninu idije Afcon to maa n waye nilẹ Afrika. Ti ọdun yii ko yatọ si tatẹyinwa. Koda oju awọn ololufẹ ere bọọlu n bẹ lọna nitori awọn ikọ meji to rapala de aṣekagba yii, ina piti ni wọn. Egypt ati Senegal ni yoo dijọ waako lọjọ Aiku lati mọ ẹni ti wọn yoo de lade Ọba ere bọọlu ni Afrika. Ni bayi, wọn ti gba ifẹsẹwọnsẹ mọkanlelaadọta ninu idije Afcon Cameroon 2021, ti papa iṣere Paul Biya to wa ni Olembe yoo si gbalejo asekagba naa. Ẹ jẹ ki a se agbeyẹwo awọn ikọ mejeeji ati iru aṣeyọri ti wọn ti ni ṣẹyin ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ yii. Odu ni Egypt nibi ka maa gba ife ẹyẹ Afcon: Ni meni meji, ba ba ni ka maa ka, Egypt ti gba ife ẹyẹ Afcon ni igba meje ọtọọtọ. Ninu akọsilẹ, ko si orileede miran ni Afrika to sunmọ wọn tabi to gba ife ẹyẹ yii ju wọn lọ. Ọdun 2010 ni wọn gba ife ẹyẹ naa kẹyin pẹlu bi wọn ti ṣe fagba han Black Stars Ghana pẹlu goolu kan sodo ninu aṣekagba. Ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba lati le fi kopa ninu idije Afcon, ta mọ si ''qualifiers'' ami ayo mejila ni wọn ko jọ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹfaa. Wọn lewaju isọri Keje lati le fi kopa ninu idije Afcon 2021. Nigba ti wọn de idije naa, Naijiria da wọn lagbo sina pẹlu goolu kan sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ isọri kẹrin. Ifidirẹmi yii dabi ẹni pe wọn ko ni tẹsiwaju ṣugbọn wọn gbọnra nu, ti wọn si gbiyanju titi ti wọn fi de aṣekagba. Senegal naa ko kẹrẹ, o ni atamátàsé ati adẹ̀yìnmú gidi: Orileede Senegal le ma gborukọ lori bi ti Egypt ṣugbọn awọn naa kii se aimọ lawujọ awọn orilẹede agbabọọlu ni Afrika. Ninu ifẹsẹwọnsẹ mejila ti wọn gba lera wọn, wọn ko fidi rẹmi ninu wọn. Wọn jawe olubori ninu mẹsan, wọn si gba ọmi ninu mẹta. Goolu mẹrinlelogun ni wọn ti jẹ lati oṣu Keje ọdun to kọja ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn kopa ninu rẹ, ti goolu mẹfa pere si wọle si awọn wọn. Bi a ba ni ka sọ nipa ikọ to ni atamatase ati awọn adẹyinmu ti ko kẹrẹ rara, Senegal jẹ ikọ to duro wamu wamu. Lọdun yii ohun to wa lọkan wọn ni bi wọn yoo se ṣaseyọri ninu aṣekagba. Lọdun 2002, Cameroon lo fidi wọn rẹmi ninu aṣekagba nipa pẹnariti, ti Algeria naa si gbewuro soju wọn ni Egypt pẹlu goolu kan sodo. Ninu irinajo wọn de aṣekagba lọdun yii, wọn ko jẹ goolu pupọ ni ipele kini ṣugbọn wọn tẹsiwajulati leke isọri keji. Igba ti wọn de abala komẹsẹoyọ ni wọn bẹrẹ si ni pitu. Goolu meji ni wọn fi da bantẹ iya fun Cape Verde lati ọwọ Sadio Mane ati Ahmadou Bamba Dieng. Equitorial Guinea naa gba igbaju ati igbamu lọwọ wọn pẹlu goolu mẹta sookan. Nigba ti Burkina Faso koju wọn ni abala to kangun si aṣekagba, goolu mẹta sookan lawọn naa fi gbara. Nkan to ku bayi ni ki wọn koju Egypt ni aṣekagba. Boya wọn yoo gba ife yẹ Afcon ni igba akọkọ ninu itan orileede wọn. Bo ti lẹ jẹ wi pe orileede meji ni yoo koju ara wọn, orukọ awọn agbabọọlu mejeeji yii, Sadio Mane ati Mo Salah lawọn eeyan n ran lẹnu. Idi ni pe awọn mejeeji jijọ n ṣe ọrọ aje pẹlu ẹgbẹ agbagbọọlu Liverpool nilẹ Gẹẹsi ni. Atamatase lawọn mejeeji, ti wọn si ti jijọ gba ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ ni Afrika. Ti Senegal yoo ba bori Egypt, Sadio Mane yoo ni ipa ribiribi lati ko nipa didoju ija kọ awọn adilemu Egypt. Amọ Salah naa ko ni gbẹni wa nitori pe oun naa yoo ja fita fita lati se bii ọkunrin. Ipade wa di ori papa nirọlẹ oni lati mọ irin ti yoo tẹ fun ekeji laarin ikọ Egypt ati Senegal, Sadio Mane ati Mo Salah, ẹ ku oju lọna. | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-60273780 |
5sports
| NBA election 2020: Olumide Akpata di aàrẹ àjọ àwọn agbẹjọ́rò ní Nàìjíríà, Taiwo Taiwo, Ajibade àtàwọn míì kíi kú oríire | Aarẹ ajọ awọn Amofin ni Naijiria, (NBA) ti paarọ ọwọ. Ẹni ti ko tii gba oye imọ ijinlẹ ninu akọsẹmọsẹ ofin ni oye naa ja mọ lọwọ. Orukọ e ni Ọgbẹni Olumide Akpata Won se ikede yi ni nkan bi ago kan oru Ọjọbọ Lati ọdọ Alaga awọn to n ri si eto idibo awon amofin, Ọgbeni Taiwo Taiwo (SAN). Akpata gbe gba oroke pẹlu iwọn ida aadọta ninu ọgọrun un Ọgbeni Babatunde Ajibade ni ẹni to tun tẹ le Ogbeni Akpata ninu eto idibo naa pẹlu ida mẹtalelogun ninu ọgọrun un Eeyan Ogoji ni ko kopa ninu eto idibo naa, ti isiro gbogbo oludibo si jẹ 16,519 29,636 ni akpapọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ ti o ko ipa ninu idibo naa. Awon ipo to ku ti won dije fun ni igba keji aare akọkọ ati ẹkeji, akọwe apapọ ,igba keji akọwe, akapo ati bẹẹ bẹẹ lọ. Awon ti won jọ dije dupo ni Diakoni Dele Adesina (SAN) ati Omọwe Babatunde Ajibade (SAN). Awọn miran ti wọn tun dije dupo mii ni: Ogbẹni John Martin fun ipo igbakeji akọkọ: Ogbẹni Adeyemo Kazeem fun igbakeji ẹkeji: Arabinrin Joyce Oduah, akọwe apapọ ati awọn mii Mọ̀ diẹ sii nipa Olumide Akpata: Akpata jẹ agbẹjọro to n soju awon oloko owo ati onisẹ aje. O tun jẹ ẹni akọkọ ti ko gba oye imọ ijinlẹ ninu ofin ti yoo fi di akosemose (SAN) to dije dupo aarẹ to si wọle lati ọdun 1989 nigba ti oloogbe Alao Aka-Bashorun fi n dari gbogbo eto tẹlẹ. Ajibade sọ ninu ọrọ rẹ pe: "Mo ti pe Olumide lati kii ku oriire gege bii Aare wa to jẹ́ ọgbọn iru aarẹ bee. ninu eto idibo to waye loojo kokandinlogbon si ogbon ọjọ, osu keje, ọdun 2020 | NBA election 2020: Olumide Akpata di aàrẹ àjọ àwọn agbẹjọ́rò ní Nàìjíríà, Taiwo Taiwo, Ajibade àtàwọn míì kíi kú oríire Aarẹ ajọ awọn Amofin ni Naijiria, (NBA) ti paarọ ọwọ. Ẹni ti ko tii gba oye imọ ijinlẹ ninu akọsẹmọsẹ ofin ni oye naa ja mọ lọwọ. Orukọ e ni Ọgbẹni Olumide Akpata Won se ikede yi ni nkan bi ago kan oru Ọjọbọ Lati ọdọ Alaga awọn to n ri si eto idibo awon amofin, Ọgbeni Taiwo Taiwo (SAN). Akpata gbe gba oroke pẹlu iwọn ida aadọta ninu ọgọrun un Ọgbeni Babatunde Ajibade ni ẹni to tun tẹ le Ogbeni Akpata ninu eto idibo naa pẹlu ida mẹtalelogun ninu ọgọrun un Eeyan Ogoji ni ko kopa ninu eto idibo naa, ti isiro gbogbo oludibo si jẹ 16,519 29,636 ni akpapọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ ti o ko ipa ninu idibo naa. Awon ipo to ku ti won dije fun ni igba keji aare akọkọ ati ẹkeji, akọwe apapọ ,igba keji akọwe, akapo ati bẹẹ bẹẹ lọ. Awon ti won jọ dije dupo ni Diakoni Dele Adesina (SAN) ati Omọwe Babatunde Ajibade (SAN). Awọn miran ti wọn tun dije dupo mii ni: Ogbẹni John Martin fun ipo igbakeji akọkọ: Ogbẹni Adeyemo Kazeem fun igbakeji ẹkeji: Arabinrin Joyce Oduah, akọwe apapọ ati awọn mii Mọ̀ diẹ sii nipa Olumide Akpata: Akpata jẹ agbẹjọro to n soju awon oloko owo ati onisẹ aje. O tun jẹ ẹni akọkọ ti ko gba oye imọ ijinlẹ ninu ofin ti yoo fi di akosemose (SAN) to dije dupo aarẹ to si wọle lati ọdun 1989 nigba ti oloogbe Alao Aka-Bashorun fi n dari gbogbo eto tẹlẹ. Ajibade sọ ninu ọrọ rẹ pe: "Mo ti pe Olumide lati kii ku oriire gege bii Aare wa to jẹ́ ọgbọn iru aarẹ bee. ninu eto idibo to waye loojo kokandinlogbon si ogbon ọjọ, osu keje, ọdun 2020 | https://www.bbc.com/yoruba/53615709 |
3politics
| Tinubu fí MC Oluomo sínú ìgbìmọ̀ ìpolongo ìdìbò Ààrẹ | Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti fi orukọ alaga igbimọ alamojuto gareeji ọkọ nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya ti ọpọlọpọ mọ si MC Oluomo, sinu igbimọ ipolongo ibo aarẹ lọdun 2023. MC Oluomo kede ọrọ naa loju opo ayelujara Instagram rẹ lẹyin to tẹwọgba iwe ipe ti akọwe igbimọ, James Falake bu wọlu . Oluomo ni pẹlu idunu ati ayo ni oun fi gba iwe ipe naa lati jẹ ọkan lara igbimọ ti yoo sisẹ pọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC lati ri pe wọn ṣe aṣeyori ninu eto idibo aarẹ lọdun 2023. “Mo gba lẹta lati jẹ ọkan lara awọn igbimọ to n ṣe agbatẹru ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC. “Pẹlu idunu ati ayọ ni mo fi dupẹ lọwọ awọn alasẹ ati awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC fun bi wọn se ka mi yẹ yii. Mo si n ṣe ileri fun yin pe ma a sisẹ karakara lati ri pe oludije wa, to jẹ oloore ati baba isalẹ mi, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ṣe aṣeyori. “Mo ti pinu ọkan mi, ma a si sa gbogbo ipa mi ni ọna to ba ofin mu lati mu ileri ẹgbẹ wa si imusẹ. “Mo wa n rọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC lati fọwọsowọpọ pẹlu gbogbo oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, ka le jọ ṣe aṣeyori.” | Tinubu fí MC Oluomo sínú ìgbìmọ̀ ìpolongo ìdìbò Ààrẹ Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti fi orukọ alaga igbimọ alamojuto gareeji ọkọ nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya ti ọpọlọpọ mọ si MC Oluomo, sinu igbimọ ipolongo ibo aarẹ lọdun 2023. MC Oluomo kede ọrọ naa loju opo ayelujara Instagram rẹ lẹyin to tẹwọgba iwe ipe ti akọwe igbimọ, James Falake bu wọlu . Oluomo ni pẹlu idunu ati ayo ni oun fi gba iwe ipe naa lati jẹ ọkan lara igbimọ ti yoo sisẹ pọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC lati ri pe wọn ṣe aṣeyori ninu eto idibo aarẹ lọdun 2023. “Mo gba lẹta lati jẹ ọkan lara awọn igbimọ to n ṣe agbatẹru ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC. “Pẹlu idunu ati ayọ ni mo fi dupẹ lọwọ awọn alasẹ ati awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC fun bi wọn se ka mi yẹ yii. Mo si n ṣe ileri fun yin pe ma a sisẹ karakara lati ri pe oludije wa, to jẹ oloore ati baba isalẹ mi, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ṣe aṣeyori. “Mo ti pinu ọkan mi, ma a si sa gbogbo ipa mi ni ọna to ba ofin mu lati mu ileri ẹgbẹ wa si imusẹ. “Mo wa n rọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC lati fọwọsowọpọ pẹlu gbogbo oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, ka le jọ ṣe aṣeyori.” | https://www.bbc.com/yoruba/articles/c10m15gyp88o |
1entertainment
| Mike Bamiloye: Inú bí mi sí fíìmù ayé tí Ogunde, Baba Sala àti Ade-Love máa ń ṣe ni mo fi bẹ̀rẹ̀ sinimá ẹ̀mí | Gbajúgbajà òṣèré sinimá nilana ẹsin Kristẹni, tii tun se olùdásílẹ̀ ẹgbẹ osere Mount Zion Ministry, Mike Bamiloye, tí ṣàlàyé lórí bí òun ṣe bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe sinimá àti àwọn ìpèníjà tí òun ti kojú nígbà náà. Bamiloye, tii se ẹni ọdún mọ́kànlelọ́gọ́ta náà ló bọ́ sójú òpó instagram rẹ̀ láti ṣàlàyé bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ìdásílẹ̀ ileesẹ iransẹ Mount Zion Ministry. Ó ní ọmọ ọdún márùn-úndinlọ́gbọ́n ni òun, nígbà tí òun wo fíìmù India kan tí ó ń fi títóbi oṣó àti ajẹ́ hàn nínú sinimá náà, àti pé èyí ló bí òun nínú láti gbaná jẹ fún Ọlọ́run. "Àkòrí fíìmù náà ni "WHEN THE POWER CHANGE Hands", mo wo sinima naa nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún márùn-úndinlọ́gbọ́n lọdún 1985, mò si ń gbóná fún Ọlọ́run pẹ̀lú ìran àgbàyanu láti sìn. A ṣẹ̀ṣẹ̀ dá Mount Zion Ministry silẹ ni, a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe ètò ìpàdé àdúrà ni. Mo ní amóhùnmáwòràn aláwọ̀ dúdú àti funfun nígbà náà, tí mo gbé si ori àpótí nínú yàrá kan tí mo ń gbé. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, mo wo sinimá India kan tí ó sì ká mì lára láti ìbẹ̀rẹ̀ de òpin. Láti ìbẹ̀rẹ̀ eré náà dé òpin ni mo fi ọkàn sí ṣùgbọ́n nígbà tí mo wòó tán, mo bú sẹ́kún, mo sá lọ sí àárín ọ̀dẹdẹ̀ ilé mi mo wa n kígbe lóhùn rara. "Jésù! lo mi! Jésù! Mo fẹ́ ṣe sinimá fún ọ! Na ọwọ rẹ lé mi kì ó lò mi! Ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe sinimá fún ọ!" Bamiloye ni kò ye òun bí òun yóò ṣe wo sinimá tí kìí se tí ẹ̀mí, tí ìsọjí yóò sì bẹ́ sílẹ̀ nínú ayé oun. Ó ní òun ti o wu òun jùlọ ni láti ṣe sinimá fún Ọlọ́run, ti èyí sì ń gbòòrò sì lojojumọ́ "Inú ń bí mi sí gbogbo àwọn sinimá ayé tí wọ́n ń ṣe nígbà yẹn, kò tíì sí Nollywood nígbà náà" Ṣùgbọ́n àwọn sinimá Hubert Ogunde bí Aiye, Jayesinmi, Aropin-Nteniyan, Ayanmo. Àti fíìmù Moses Olaiya (Baba Sala) bi: Mosebolatan, Orun Mooru, Diamond, àti àwọn fíìmù tí Ade Afolayan (ADE Love) ṣe bi Taxi Driver." Gbajúgbajà òṣèré tó ṣe sinimá Abejoye tun ṣàlàyé pé, ní àsìkò náà kò sí Nollywood ṣùgbọ́n iná Jésù ń jó gidi nínú òun. O ni inu a máa bí òun sì àwọn sinimá tí wọn máa fi ń hàn ní ilé ìjọsìn lásìkò ìsọjí, tí ènìyàn kò ní gbọ́ nnkan ti àwọn oyinbo ń sọ, tí ẹni tó ṣe òngbifọ̀ náà yóò máa sọ ń kan tó bá bọ́ síi lẹ́nu Ó ní èyí gan ni àwọn nǹkan tí ó má ń bí òun nínú, ti oun se fẹ́ sinimá tí Naijiria fún àwọn Kristẹni. "Mo lọ sí ọgbà ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Ife ni gbọ̀ngàn Odùduwà nígbà naa, lati lọ wo sinimá Hubert Ogunde tí àkọlé rẹ ń jẹ́ AIYE. Lẹ́yìn tí sinimá náà tan ní bí aago mọ́kànlá alẹ́, mo jáde ní gbọ̀ngàn náà báyìí, ọkàn mi kún fún èrò láti ṣe nǹkan fún Jésù ni, inú mi bajẹ́ gidi." Amọ lẹyin akoko naa ni Mike Bamiloye gbe ọpọ sinima ẹmi jade, ninu rẹ si ni sinima olokiki ‘Agbara Nla’, to se afihan bi agbara Jesu se ju agbara awọn mi okunkun lọ. | Mike Bamiloye: Inú bí mi sí fíìmù ayé tí Ogunde, Baba Sala àti Ade-Love máa ń ṣe ni mo fi bẹ̀rẹ̀ sinimá ẹ̀mí Gbajúgbajà òṣèré sinimá nilana ẹsin Kristẹni, tii tun se olùdásílẹ̀ ẹgbẹ osere Mount Zion Ministry, Mike Bamiloye, tí ṣàlàyé lórí bí òun ṣe bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe sinimá àti àwọn ìpèníjà tí òun ti kojú nígbà náà. Bamiloye, tii se ẹni ọdún mọ́kànlelọ́gọ́ta náà ló bọ́ sójú òpó instagram rẹ̀ láti ṣàlàyé bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ìdásílẹ̀ ileesẹ iransẹ Mount Zion Ministry. Ó ní ọmọ ọdún márùn-úndinlọ́gbọ́n ni òun, nígbà tí òun wo fíìmù India kan tí ó ń fi títóbi oṣó àti ajẹ́ hàn nínú sinimá náà, àti pé èyí ló bí òun nínú láti gbaná jẹ fún Ọlọ́run. "Àkòrí fíìmù náà ni "WHEN THE POWER CHANGE Hands", mo wo sinima naa nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún márùn-úndinlọ́gbọ́n lọdún 1985, mò si ń gbóná fún Ọlọ́run pẹ̀lú ìran àgbàyanu láti sìn. A ṣẹ̀ṣẹ̀ dá Mount Zion Ministry silẹ ni, a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe ètò ìpàdé àdúrà ni. Mo ní amóhùnmáwòràn aláwọ̀ dúdú àti funfun nígbà náà, tí mo gbé si ori àpótí nínú yàrá kan tí mo ń gbé. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, mo wo sinimá India kan tí ó sì ká mì lára láti ìbẹ̀rẹ̀ de òpin. Láti ìbẹ̀rẹ̀ eré náà dé òpin ni mo fi ọkàn sí ṣùgbọ́n nígbà tí mo wòó tán, mo bú sẹ́kún, mo sá lọ sí àárín ọ̀dẹdẹ̀ ilé mi mo wa n kígbe lóhùn rara. "Jésù! lo mi! Jésù! Mo fẹ́ ṣe sinimá fún ọ! Na ọwọ rẹ lé mi kì ó lò mi! Ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe sinimá fún ọ!" Bamiloye ni kò ye òun bí òun yóò ṣe wo sinimá tí kìí se tí ẹ̀mí, tí ìsọjí yóò sì bẹ́ sílẹ̀ nínú ayé oun. Ó ní òun ti o wu òun jùlọ ni láti ṣe sinimá fún Ọlọ́run, ti èyí sì ń gbòòrò sì lojojumọ́ "Inú ń bí mi sí gbogbo àwọn sinimá ayé tí wọ́n ń ṣe nígbà yẹn, kò tíì sí Nollywood nígbà náà" Ṣùgbọ́n àwọn sinimá Hubert Ogunde bí Aiye, Jayesinmi, Aropin-Nteniyan, Ayanmo. Àti fíìmù Moses Olaiya (Baba Sala) bi: Mosebolatan, Orun Mooru, Diamond, àti àwọn fíìmù tí Ade Afolayan (ADE Love) ṣe bi Taxi Driver." Gbajúgbajà òṣèré tó ṣe sinimá Abejoye tun ṣàlàyé pé, ní àsìkò náà kò sí Nollywood ṣùgbọ́n iná Jésù ń jó gidi nínú òun. O ni inu a máa bí òun sì àwọn sinimá tí wọn máa fi ń hàn ní ilé ìjọsìn lásìkò ìsọjí, tí ènìyàn kò ní gbọ́ nnkan ti àwọn oyinbo ń sọ, tí ẹni tó ṣe òngbifọ̀ náà yóò máa sọ ń kan tó bá bọ́ síi lẹ́nu Ó ní èyí gan ni àwọn nǹkan tí ó má ń bí òun nínú, ti oun se fẹ́ sinimá tí Naijiria fún àwọn Kristẹni. "Mo lọ sí ọgbà ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Ife ni gbọ̀ngàn Odùduwà nígbà naa, lati lọ wo sinimá Hubert Ogunde tí àkọlé rẹ ń jẹ́ AIYE. Lẹ́yìn tí sinimá náà tan ní bí aago mọ́kànlá alẹ́, mo jáde ní gbọ̀ngàn náà báyìí, ọkàn mi kún fún èrò láti ṣe nǹkan fún Jésù ni, inú mi bajẹ́ gidi." Amọ lẹyin akoko naa ni Mike Bamiloye gbe ọpọ sinima ẹmi jade, ninu rẹ si ni sinima olokiki ‘Agbara Nla’, to se afihan bi agbara Jesu se ju agbara awọn mi okunkun lọ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58410705 |
5sports
| Kazeem Tiamiyu: Wọ́n ti sin òkú agbábọ́ọ̀lù Remo Stars tí wọ́n sọ pé SARS pa ní Sagamu | Wọn ti sin oku agbabọọlu, Kazeem Tiamiyu, ti iṣẹlẹ iku rẹ fa iwọde nilu Sagamu nipinlẹ Ogun, ṣugbọn awọn ibeere kan ṣi n jẹyọ lori iku to pa a. Ẹni ọdun mọkanlelogun ọhun, to n gba bọọlu fun Remo Stars, ni ọkọ gba, to si gba ibẹ ku, ṣugbọn ẹgbẹ agbabọọlu rẹ sọ pe awọn ọlọpaa lo pa a. Ọrẹ rẹ kan naa to sọ pe iṣẹlẹ naa ṣoju ohun naa sọ fun BBC pe awọn ọlọpaa SARS lo ṣokunfa iku rẹ. Nibi eto isinku na to waye ni Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ni awọn ẹbi, ọrẹ ati akẹẹgbẹ rẹ ti kopa, wọn si wọ Tiamiyu ni aṣọ funfun, ti wọn si sin ni ilana ẹsin Islam. Agboole ẹbi rẹ to wa ni Ajaka nilu Sagamu nipinlẹ Ogun ni wọn sin si. Ṣe ko si obi to gbadura lati f'oju sunkun ọmọ, ẹ gbọ nkan ti awọn obi oloogbe Tiamiyu ba BBC Yoruba sọrọ nipa rẹ. Aarẹ ẹgbẹ agbabọọlu Remo Stars, Kunle Soname, ati Aarẹ ajọ to n mojuto bọọlu gbigba ni Naijiria, NFF, Amaju Pinnick naa ti lọ ba ẹbi oloogbe kẹdun l'ọsẹ yii. Jakejado Naijiria ni awọn eniyan ti koro oju si iru iku to pa Tiamiyu, nitori bi iroyin ṣe sọ pe lasiko ti awọn ọlọpaa SARS da a duro sinu ọkọ wọn lo pade iku ojiji. Eyi si mu ki ọpọlọpọ olugbe ilu Sagamu ṣe iwọde, ti awọn eniyan fi n beere fun idajọ ati ipolongo pe ki wọn o pa ẹka ọlọpaa SARS rẹ. Eniyan mẹta si ni iroyin tun sọ pe o padanu ẹmi wọn nibi iwọde naa, ti awọn ọlọpaa si sọ pe awọn ṣi n ṣe iwadii awọn ẹsun yii. Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọlọpaa to lọwọ si iṣẹlẹ naa ti wa ni ihamọ, ati pe wọn ti gbe e lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ti n ṣewadi iwa ọdaran. Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba sọ fun BBC pe "iwadii ṣi n lọ lọwọ, ileri wa si awọn ọmọ Naijiria si ni pe a ko ni ṣe mago-mago tabi fi ohunkohun pams nipa iwadii naa". | Kazeem Tiamiyu: Wọ́n ti sin òkú agbábọ́ọ̀lù Remo Stars tí wọ́n sọ pé SARS pa ní Sagamu Wọn ti sin oku agbabọọlu, Kazeem Tiamiyu, ti iṣẹlẹ iku rẹ fa iwọde nilu Sagamu nipinlẹ Ogun, ṣugbọn awọn ibeere kan ṣi n jẹyọ lori iku to pa a. Ẹni ọdun mọkanlelogun ọhun, to n gba bọọlu fun Remo Stars, ni ọkọ gba, to si gba ibẹ ku, ṣugbọn ẹgbẹ agbabọọlu rẹ sọ pe awọn ọlọpaa lo pa a. Ọrẹ rẹ kan naa to sọ pe iṣẹlẹ naa ṣoju ohun naa sọ fun BBC pe awọn ọlọpaa SARS lo ṣokunfa iku rẹ. Nibi eto isinku na to waye ni Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ni awọn ẹbi, ọrẹ ati akẹẹgbẹ rẹ ti kopa, wọn si wọ Tiamiyu ni aṣọ funfun, ti wọn si sin ni ilana ẹsin Islam. Agboole ẹbi rẹ to wa ni Ajaka nilu Sagamu nipinlẹ Ogun ni wọn sin si. Ṣe ko si obi to gbadura lati f'oju sunkun ọmọ, ẹ gbọ nkan ti awọn obi oloogbe Tiamiyu ba BBC Yoruba sọrọ nipa rẹ. Aarẹ ẹgbẹ agbabọọlu Remo Stars, Kunle Soname, ati Aarẹ ajọ to n mojuto bọọlu gbigba ni Naijiria, NFF, Amaju Pinnick naa ti lọ ba ẹbi oloogbe kẹdun l'ọsẹ yii. Jakejado Naijiria ni awọn eniyan ti koro oju si iru iku to pa Tiamiyu, nitori bi iroyin ṣe sọ pe lasiko ti awọn ọlọpaa SARS da a duro sinu ọkọ wọn lo pade iku ojiji. Eyi si mu ki ọpọlọpọ olugbe ilu Sagamu ṣe iwọde, ti awọn eniyan fi n beere fun idajọ ati ipolongo pe ki wọn o pa ẹka ọlọpaa SARS rẹ. Eniyan mẹta si ni iroyin tun sọ pe o padanu ẹmi wọn nibi iwọde naa, ti awọn ọlọpaa si sọ pe awọn ṣi n ṣe iwadii awọn ẹsun yii. Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọlọpaa to lọwọ si iṣẹlẹ naa ti wa ni ihamọ, ati pe wọn ti gbe e lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ti n ṣewadi iwa ọdaran. Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba sọ fun BBC pe "iwadii ṣi n lọ lọwọ, ileri wa si awọn ọmọ Naijiria si ni pe a ko ni ṣe mago-mago tabi fi ohunkohun pams nipa iwadii naa". | https://www.bbc.com/yoruba/51677681 |
3politics
| PDP ṣetán láti kéde olùdíje igbákejì ààrẹ fún Atiku | Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Iyiochia Ayu ti ni ki awọn eniyan ni igbagbọ ninu ẹgbẹ ati oludije fun ipo aarẹ, Atiku Abubakar lori ẹni ti yoo dije gẹgẹ bi igbakeji rẹ. Ayu ni laarin wakati mejidinlaadọta naa ni awọn yoo fi le ẹni ti yoo dije igbakeji naa lede. Lasiko ipade pẹlu ajọ to n ṣakoso ijiroro lori ẹni ti wọn yoo gbe fun igbakeji Atiku naa lo sọ bẹẹ. O ni ijiroro naa da le ẹni ti wọn yoo gbe lati dije igbakeji aarẹ naa pẹlu Atiku Abubakar. ‘’Laarin wakati mejidinlaadọta, a o sọ ẹni ti yoo dije du ipo igbakeji aarẹ naa’’ Lara awọn to wa nibi ijiroro naa ni Alaga ẹgbẹ awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Aminu Tambuwal; Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed; gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom; Ati Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin tẹlẹ, David Mark; gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹri, Olusegun Mimiko; gomina ipinlẹ Cross River tẹlẹ, Liyel Imoke, tofimọ Sẹnatọ Philip Aduda ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ajọ Eleto Idibo ni Naijiria,INEC ti fun gbogbo ẹgbẹ oṣelu di Ọjọ Kẹtadinlogun, Oṣu Kẹfa lati ṣe iforukọ silẹ gbogbo awọn oludije ati igbakeji wọn. | PDP ṣetán láti kéde olùdíje igbákejì ààrẹ fún Atiku Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Iyiochia Ayu ti ni ki awọn eniyan ni igbagbọ ninu ẹgbẹ ati oludije fun ipo aarẹ, Atiku Abubakar lori ẹni ti yoo dije gẹgẹ bi igbakeji rẹ. Ayu ni laarin wakati mejidinlaadọta naa ni awọn yoo fi le ẹni ti yoo dije igbakeji naa lede. Lasiko ipade pẹlu ajọ to n ṣakoso ijiroro lori ẹni ti wọn yoo gbe fun igbakeji Atiku naa lo sọ bẹẹ. O ni ijiroro naa da le ẹni ti wọn yoo gbe lati dije igbakeji aarẹ naa pẹlu Atiku Abubakar. ‘’Laarin wakati mejidinlaadọta, a o sọ ẹni ti yoo dije du ipo igbakeji aarẹ naa’’ Lara awọn to wa nibi ijiroro naa ni Alaga ẹgbẹ awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Aminu Tambuwal; Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed; gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom; Ati Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin tẹlẹ, David Mark; gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹri, Olusegun Mimiko; gomina ipinlẹ Cross River tẹlẹ, Liyel Imoke, tofimọ Sẹnatọ Philip Aduda ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ajọ Eleto Idibo ni Naijiria,INEC ti fun gbogbo ẹgbẹ oṣelu di Ọjọ Kẹtadinlogun, Oṣu Kẹfa lati ṣe iforukọ silẹ gbogbo awọn oludije ati igbakeji wọn. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/c3gqq75z75zo |
5sports
| Hijab Female Footballer: Zulfah ní àlá òun ní láti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tó dáńtọ́ | Yoruba ni ọmọ ti yoo ba jẹ Aṣamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu ṣamu-ṣamu. Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni ọdọbinrin Zulfah Abdulazzes to si n lo iboju tawọn ẹlẹsin musulumi tawọn mọ si Hijab. Amọ eyi mu ki Zulfah da yatọ lori papa gẹgẹ niwọn igba to jẹ pe isẹ bọọlu gbigba fawọn obinrin lo yan laayo. Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, ọmọdebinrin naa ni ọmọ ọdun kan ati aabọ ni oun ti n gbe lọdọ iya oun agba, ki onitọun to jade laye lọdun 2017. Akẹkọọbinrin agbabọọlu naa ni igbe aye le diẹ fun oun amọ afojusun oun ni pe lọjọ iwaju, ki oun di obinrin agbabọọlu to pegede julọ bii Azzezat Oshoala. Amọ ti ko ba si lori papa lati gba bọọlu, obi, orogbo ati suti ni Zulfah maa n ta labẹ afara Ojota, ko le ri ọwọ mu lọ si ẹnu. O wa salaye ọpọ ipenija to n koju lati awọn akẹẹgbẹ rẹ gẹgẹ bi agbabọọlu obinrin to n lo Hijab. | Hijab Female Footballer: Zulfah ní àlá òun ní láti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tó dáńtọ́ Yoruba ni ọmọ ti yoo ba jẹ Aṣamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu ṣamu-ṣamu. Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni ọdọbinrin Zulfah Abdulazzes to si n lo iboju tawọn ẹlẹsin musulumi tawọn mọ si Hijab. Amọ eyi mu ki Zulfah da yatọ lori papa gẹgẹ niwọn igba to jẹ pe isẹ bọọlu gbigba fawọn obinrin lo yan laayo. Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, ọmọdebinrin naa ni ọmọ ọdun kan ati aabọ ni oun ti n gbe lọdọ iya oun agba, ki onitọun to jade laye lọdun 2017. Akẹkọọbinrin agbabọọlu naa ni igbe aye le diẹ fun oun amọ afojusun oun ni pe lọjọ iwaju, ki oun di obinrin agbabọọlu to pegede julọ bii Azzezat Oshoala. Amọ ti ko ba si lori papa lati gba bọọlu, obi, orogbo ati suti ni Zulfah maa n ta labẹ afara Ojota, ko le ri ọwọ mu lọ si ẹnu. O wa salaye ọpọ ipenija to n koju lati awọn akẹẹgbẹ rẹ gẹgẹ bi agbabọọlu obinrin to n lo Hijab. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58647862 |
4religion
| Enoch Adeboye: "Daddy, ẹ jẹ́ kí Ọlọrun gbé yín" ní ọ̀rọ̀ tó tú mí nínú kúrò nínú ọ̀fọ̀ ọmọ mi | Pasitọ agba ijọ Reedmed Christian Church of God, Enoch Adeboye, ti sọrọ lori bi ibanujẹ rẹ se dopin nigba ti ọmọ rẹ kan ku lọdun 2021. Gẹgẹ bi ọrọ to sọ, o ni atẹjiṣẹ kan ṣoṣo ti ẹnikan fi ranṣẹ, lo yi ọkan oun pada, lẹyin ti Dare ku. Oṣu Karun-un, ọdun 2021 ni Dare Adeboye, to jẹ ẹni ọdun mejilelogoji ku loju orun rẹ nilu Eket, nibi to n gbe nipinlẹ Akwa Ibom. Ilu naa lo ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi alufaa kan ninu ijọ Redeem. Nigba to n sọrọ nibi ipade adura oloṣooṣu ijọ naa fun ti oṣu Kẹrin, Pasitọ Adeboye sọ pe inu ibanujẹ nla ni oun wa lẹyin iku ọmọ oun, Dare. O ni ṣugbọn nnkan yipada nigba ti ọmọ oun kan ninu igbagbọ, fi atẹjiṣẹ kan ranṣẹ si ori ẹrọ ibanisọrọ oun pe "Daddy, ẹ jẹ́ kí Ọlọrun kí o gbé yín". O ni ọrọ naa lo yi ọkan oun pada, ti oun fi pa ibanujẹ ti, ti oun si gba ki Ọlọrun gbe oun, nitori pe oun lo ma n ba ẹda gbe iṣoro, ibanujẹ, ati wahala, niwọn igba ti eeyan ba ti jẹ ọmọ rẹ. Ọjọ Kẹfa, oṣu Karun-un, ọdun 2021, ni iroyin jade pe Dare Adeboye, to jẹ ọmọ kẹta fun Pasitọ Enoch Adeboye ti ku. Amọ, o ti ku lati ọjọ kẹrin, oṣu Karun-un. Iroyin sọ pe o sun, ni ko ji mọ ni oru mọju ọjọ naa. Gẹgẹ bi ikede ti ẹbi fi sita, oloogbe naa ko ṣaisan, tabi ni aarun kankan ṣaaju iku rẹ. Eyi ti iroyin sọ pe o mu ki awọn agba alufaa inu ijọ naa gba adura kikan, pe boya yoo ji pada, niwọn igba ti ko ṣaisan tẹlẹ. Wọn bi Dare Adeboye ni ọjọ kẹsan an, oṣu Kẹfa, ọdun 1979. Dare jẹ olukọ awọn ọdọ, o si tun jẹ ọkan pataki lara awọn ọdọ to lẹnu lọrọ ati ilumọka ninu ijọ RCCG. O ti fi igba kan ri ṣiṣẹ gẹgẹ bii Pasitọ lori ijọ RCCG House of Praise, to wa ni Birmingham, nilẹ Gẹẹsi. Bẹẹ naa lo tun ṣiṣẹ gẹgẹ bii pasitọ ijọ naa, ẹka ti awọn ọdọ to wa ni Ipinlẹ Kaduna. Ki ọlọjọ to de, oun ni pasitọ gbogbogbo fun awọn ọdọ ni RCCG fun ẹkun Niger, Benue, Kwara, Kogi, Nasrawa, Plateua ati Abuja. | Enoch Adeboye: "Daddy, ẹ jẹ́ kí Ọlọrun gbé yín" ní ọ̀rọ̀ tó tú mí nínú kúrò nínú ọ̀fọ̀ ọmọ mi Pasitọ agba ijọ Reedmed Christian Church of God, Enoch Adeboye, ti sọrọ lori bi ibanujẹ rẹ se dopin nigba ti ọmọ rẹ kan ku lọdun 2021. Gẹgẹ bi ọrọ to sọ, o ni atẹjiṣẹ kan ṣoṣo ti ẹnikan fi ranṣẹ, lo yi ọkan oun pada, lẹyin ti Dare ku. Oṣu Karun-un, ọdun 2021 ni Dare Adeboye, to jẹ ẹni ọdun mejilelogoji ku loju orun rẹ nilu Eket, nibi to n gbe nipinlẹ Akwa Ibom. Ilu naa lo ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi alufaa kan ninu ijọ Redeem. Nigba to n sọrọ nibi ipade adura oloṣooṣu ijọ naa fun ti oṣu Kẹrin, Pasitọ Adeboye sọ pe inu ibanujẹ nla ni oun wa lẹyin iku ọmọ oun, Dare. O ni ṣugbọn nnkan yipada nigba ti ọmọ oun kan ninu igbagbọ, fi atẹjiṣẹ kan ranṣẹ si ori ẹrọ ibanisọrọ oun pe "Daddy, ẹ jẹ́ kí Ọlọrun kí o gbé yín". O ni ọrọ naa lo yi ọkan oun pada, ti oun fi pa ibanujẹ ti, ti oun si gba ki Ọlọrun gbe oun, nitori pe oun lo ma n ba ẹda gbe iṣoro, ibanujẹ, ati wahala, niwọn igba ti eeyan ba ti jẹ ọmọ rẹ. Ọjọ Kẹfa, oṣu Karun-un, ọdun 2021, ni iroyin jade pe Dare Adeboye, to jẹ ọmọ kẹta fun Pasitọ Enoch Adeboye ti ku. Amọ, o ti ku lati ọjọ kẹrin, oṣu Karun-un. Iroyin sọ pe o sun, ni ko ji mọ ni oru mọju ọjọ naa. Gẹgẹ bi ikede ti ẹbi fi sita, oloogbe naa ko ṣaisan, tabi ni aarun kankan ṣaaju iku rẹ. Eyi ti iroyin sọ pe o mu ki awọn agba alufaa inu ijọ naa gba adura kikan, pe boya yoo ji pada, niwọn igba ti ko ṣaisan tẹlẹ. Wọn bi Dare Adeboye ni ọjọ kẹsan an, oṣu Kẹfa, ọdun 1979. Dare jẹ olukọ awọn ọdọ, o si tun jẹ ọkan pataki lara awọn ọdọ to lẹnu lọrọ ati ilumọka ninu ijọ RCCG. O ti fi igba kan ri ṣiṣẹ gẹgẹ bii Pasitọ lori ijọ RCCG House of Praise, to wa ni Birmingham, nilẹ Gẹẹsi. Bẹẹ naa lo tun ṣiṣẹ gẹgẹ bii pasitọ ijọ naa, ẹka ti awọn ọdọ to wa ni Ipinlẹ Kaduna. Ki ọlọjọ to de, oun ni pasitọ gbogbogbo fun awọn ọdọ ni RCCG fun ẹkun Niger, Benue, Kwara, Kogi, Nasrawa, Plateua ati Abuja. | https://www.bbc.com/yoruba/awon-iroyin-miran-60964892 |
5sports
| AFCON 2019: Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù 24 ni yóò kópa nínú rẹ̀ | Niṣe ni eto aabo duro deede ni olu ilu Egypt, Cairo ni ọjọ Ẹti ti ayẹyẹ iṣide idije ilẹ Africa, AFCON 2019 bẹrẹ. Eyi ṣeeṣe ko ribẹ nitori bi eto aabo ṣe ri l'orilẹede naa bayi, latari bi aarẹ orilẹede naa nigba kan, Mohammed Morsi ṣe ku nile ẹjọ lasiko to n jẹjọ, ti idije naa si n waye lẹyin ọjọ diẹ ti eyi waye. Gẹgẹ bi iroyin to n lọ labẹle, awọn oṣiṣẹ alaabo to to ẹgbẹrun mẹẹdogun ni yoo ṣiṣẹ ni awọn ilu mẹrẹẹrin ti idije naa yoo ti waye; Cairo, Alexandria, Suez ati Ismailia. Bakan naa ni ibudo ayẹwo pọ yika papa iṣere ti eto naa ti waye lalẹ ọjọ Ẹti. A gbọ pe eto ayẹwo kan tun ti wa nilẹ, lati maa tọ pinpin awọn oluworan lati igba ti wọn ba ti wọ papa iṣere, titi wọn yoo fi jade. Femi Kuti, tii se ọmọ Kaarọ Oojire, to tun jẹ ilumọọka akọrin lati orilẹede Naijiria, yoo dara pọ mọ awọn gbajugbaja akọrin miran, ti yoo ma a bawọn si idije bọọlu fun ife ẹyẹ ilẹ Afirika, AFCON 2019 pẹlu orin. Orin kikọ̀ naa wa lara awọn ayẹyẹ ibẹrẹ idije Afcon naa, ti ọpọlọpọ ayẹyẹ ti yoo gbe asa ga ni ilẹ Afirika yoo rinlẹ nibi ayẹyẹ iside idije naa. Idije ti AFCON tọdun yii lo tobi ju lati ọdun 1957 to ti bẹrẹ. Ẹgbẹ agbabọọlu mẹrindinlogun ni yoo kopa fun igba akọkọ. Bakan naa fun igba akọkọ, idije naa to maa n waye laarin oṣu Kinni ọdun si oṣu Keji yoo waye, laarin oṣu Kẹfa ọdun si oṣu Keje. Eyi waye nitori bi o ṣe maa n fa ariyanjiyan laarin igbimọ ajọ to n mojuto idije naa, CAF ati awọn ẹgbẹ agbabọọlu nilẹ Yuroopu, to ni lati yọnda awọn agbabọọlu wọn fun idije naa lai jẹ pe saa bọọlu gbigba nilẹ Yuroopu ti pari. Ṣugbọn ninu oṣu Keje ọdun 2017, ajọ CAF pinnu lati sun idije ti ọdun yii si oṣu Kẹfa ati ikeje. Bakan naa ni wọn sọ ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo kopa si mẹrinlelogun. Ẹgbẹ agbabọọlu mẹrindinlogun lo maa n kopa tẹlẹ. Orilẹede Egypt lo gbalejo idije naa bayii fun igba karun un. Ẹgbẹ agbabọọlu Pharaoh ti Egypt si lo ti gba ife ẹyẹ idije naa ju lọ. O ti gba a fun igba meje. Orilẹede Cameroon lo yẹ ko gba alejo idije AFCON 2019, ṣugbọn wọn gba a kuro lọwọ wọn l'oṣu Kọkanla, ọdun 2018, nitori pe wọn ko jara mọ imurasilẹ ati eto aabo to mẹhẹ l'orilẹede naa. Oṣu Kinni ọdun 2019 ni ajọ CAF kede Egypt pe oun ni yoo gbalejo idije naa. Awọn orilẹede ti yoo kopa ninu idije naa ni Egypt, Madagascar, Tunisia, Senegal, Morocco, Nigeria, Uganda, Mali, Guinea, Algeria, Mauritania, Ivory Coast, Kenya, Ghana, Angola, Burundi, Cameroon, Guinea-Bissau, Namibia, Zimbabwe, DR Congo, Benin, Tanzania, ati South Africa. | AFCON 2019: Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù 24 ni yóò kópa nínú rẹ̀ Niṣe ni eto aabo duro deede ni olu ilu Egypt, Cairo ni ọjọ Ẹti ti ayẹyẹ iṣide idije ilẹ Africa, AFCON 2019 bẹrẹ. Eyi ṣeeṣe ko ribẹ nitori bi eto aabo ṣe ri l'orilẹede naa bayi, latari bi aarẹ orilẹede naa nigba kan, Mohammed Morsi ṣe ku nile ẹjọ lasiko to n jẹjọ, ti idije naa si n waye lẹyin ọjọ diẹ ti eyi waye. Gẹgẹ bi iroyin to n lọ labẹle, awọn oṣiṣẹ alaabo to to ẹgbẹrun mẹẹdogun ni yoo ṣiṣẹ ni awọn ilu mẹrẹẹrin ti idije naa yoo ti waye; Cairo, Alexandria, Suez ati Ismailia. Bakan naa ni ibudo ayẹwo pọ yika papa iṣere ti eto naa ti waye lalẹ ọjọ Ẹti. A gbọ pe eto ayẹwo kan tun ti wa nilẹ, lati maa tọ pinpin awọn oluworan lati igba ti wọn ba ti wọ papa iṣere, titi wọn yoo fi jade. Femi Kuti, tii se ọmọ Kaarọ Oojire, to tun jẹ ilumọọka akọrin lati orilẹede Naijiria, yoo dara pọ mọ awọn gbajugbaja akọrin miran, ti yoo ma a bawọn si idije bọọlu fun ife ẹyẹ ilẹ Afirika, AFCON 2019 pẹlu orin. Orin kikọ̀ naa wa lara awọn ayẹyẹ ibẹrẹ idije Afcon naa, ti ọpọlọpọ ayẹyẹ ti yoo gbe asa ga ni ilẹ Afirika yoo rinlẹ nibi ayẹyẹ iside idije naa. Idije ti AFCON tọdun yii lo tobi ju lati ọdun 1957 to ti bẹrẹ. Ẹgbẹ agbabọọlu mẹrindinlogun ni yoo kopa fun igba akọkọ. Bakan naa fun igba akọkọ, idije naa to maa n waye laarin oṣu Kinni ọdun si oṣu Keji yoo waye, laarin oṣu Kẹfa ọdun si oṣu Keje. Eyi waye nitori bi o ṣe maa n fa ariyanjiyan laarin igbimọ ajọ to n mojuto idije naa, CAF ati awọn ẹgbẹ agbabọọlu nilẹ Yuroopu, to ni lati yọnda awọn agbabọọlu wọn fun idije naa lai jẹ pe saa bọọlu gbigba nilẹ Yuroopu ti pari. Ṣugbọn ninu oṣu Keje ọdun 2017, ajọ CAF pinnu lati sun idije ti ọdun yii si oṣu Kẹfa ati ikeje. Bakan naa ni wọn sọ ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo kopa si mẹrinlelogun. Ẹgbẹ agbabọọlu mẹrindinlogun lo maa n kopa tẹlẹ. Orilẹede Egypt lo gbalejo idije naa bayii fun igba karun un. Ẹgbẹ agbabọọlu Pharaoh ti Egypt si lo ti gba ife ẹyẹ idije naa ju lọ. O ti gba a fun igba meje. Orilẹede Cameroon lo yẹ ko gba alejo idije AFCON 2019, ṣugbọn wọn gba a kuro lọwọ wọn l'oṣu Kọkanla, ọdun 2018, nitori pe wọn ko jara mọ imurasilẹ ati eto aabo to mẹhẹ l'orilẹede naa. Oṣu Kinni ọdun 2019 ni ajọ CAF kede Egypt pe oun ni yoo gbalejo idije naa. Awọn orilẹede ti yoo kopa ninu idije naa ni Egypt, Madagascar, Tunisia, Senegal, Morocco, Nigeria, Uganda, Mali, Guinea, Algeria, Mauritania, Ivory Coast, Kenya, Ghana, Angola, Burundi, Cameroon, Guinea-Bissau, Namibia, Zimbabwe, DR Congo, Benin, Tanzania, ati South Africa. | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-48722559 |
5sports
| Arsenal vs man United: Láì tíì pé ọ̀sẹ̀ kan tó kéde akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun, Arsenal j'ojú Man U pẹ̀lú góòlù Mẹ́ta sí ẹyọkan ní Emirate | Ọsẹ yii ṣẹnuure fun ikọ agbabọọlu Arsenal atawọn ololufẹ rẹ pẹlu bi wọn tun ṣe digbolu Manchester United lọsan ọjọ Abamẹta pẹlu goolu mẹta si ẹyọkan. Iṣẹgun ti Arsenal ri lori Manchester United yii lo gbe wọn lọ si ipo kẹrin ṣaaju Totteham to ṣi ni ifẹsẹwọnsẹ tiwọn lọsan ọjọ Abamẹta kan naa. Nuno Tavares lo kọkọ ṣide ojo goolu to rọ fun Arsenal nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju naa wọ iṣẹju kẹta. Laipẹ rẹ nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kejilelọgbọn ni Busayọ Saka ba tun fọba lee pẹlu pẹnariti lẹyin ti wọn gbe e ṣubu loju ile Manchester United. Christiano Ronaldo, to ṣẹṣẹ pada sori papa lẹyin to padanu ọmọ rẹ ọkunrin laipẹ yii, da ẹyọ kan pada ki Bruno Fernades to sọ pẹnariti nu fun Manchester United lẹyin ti Tavares fi ọwọ gbe bọọlu loju ile Arsenal. goolu ti Christiano Ronaldo gba wọ awn Arsenal yii ni yoo di goolu ọgọrun ti gbajumọ agbabọọlu naa yoo maa gba wọ awọn ni idije Premier league. Ni ọjọ kini oṣu kọkanla ọdun 2003, tii ṣe ọdun marundinlogun sẹyin ni C. Ronaldo kọkọ gba goolu si awọn ni idije Premier League ninu ifẹsẹwọnsẹ Manchester United pẹlu Portsmouth ni gbede Old Trafford Granit Xhaka lo pa oju goolu de pẹlu bọọlu to gba sawọn eyi ti ọwọ gooli manchester United, David De Gea ko to. Ten Hag ni yoo maa ṣakoso ikọ naa ni saa to n bọ. Esi ifẹsẹwọnsẹ Manchester united pẹlu Arsenal yoo si wa lara awọn ohun ti yoo maa gbe yẹwo lati mọ pe omi n bẹ laamu fun oun lasiko to ba bẹrẹ iṣẹ pẹlu wọn. | Arsenal vs man United: Láì tíì pé ọ̀sẹ̀ kan tó kéde akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun, Arsenal j'ojú Man U pẹ̀lú góòlù Mẹ́ta sí ẹyọkan ní Emirate Ọsẹ yii ṣẹnuure fun ikọ agbabọọlu Arsenal atawọn ololufẹ rẹ pẹlu bi wọn tun ṣe digbolu Manchester United lọsan ọjọ Abamẹta pẹlu goolu mẹta si ẹyọkan. Iṣẹgun ti Arsenal ri lori Manchester United yii lo gbe wọn lọ si ipo kẹrin ṣaaju Totteham to ṣi ni ifẹsẹwọnsẹ tiwọn lọsan ọjọ Abamẹta kan naa. Nuno Tavares lo kọkọ ṣide ojo goolu to rọ fun Arsenal nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju naa wọ iṣẹju kẹta. Laipẹ rẹ nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kejilelọgbọn ni Busayọ Saka ba tun fọba lee pẹlu pẹnariti lẹyin ti wọn gbe e ṣubu loju ile Manchester United. Christiano Ronaldo, to ṣẹṣẹ pada sori papa lẹyin to padanu ọmọ rẹ ọkunrin laipẹ yii, da ẹyọ kan pada ki Bruno Fernades to sọ pẹnariti nu fun Manchester United lẹyin ti Tavares fi ọwọ gbe bọọlu loju ile Arsenal. goolu ti Christiano Ronaldo gba wọ awn Arsenal yii ni yoo di goolu ọgọrun ti gbajumọ agbabọọlu naa yoo maa gba wọ awọn ni idije Premier league. Ni ọjọ kini oṣu kọkanla ọdun 2003, tii ṣe ọdun marundinlogun sẹyin ni C. Ronaldo kọkọ gba goolu si awọn ni idije Premier League ninu ifẹsẹwọnsẹ Manchester United pẹlu Portsmouth ni gbede Old Trafford Granit Xhaka lo pa oju goolu de pẹlu bọọlu to gba sawọn eyi ti ọwọ gooli manchester United, David De Gea ko to. Ten Hag ni yoo maa ṣakoso ikọ naa ni saa to n bọ. Esi ifẹsẹwọnsẹ Manchester united pẹlu Arsenal yoo si wa lara awọn ohun ti yoo maa gbe yẹwo lati mọ pe omi n bẹ laamu fun oun lasiko to ba bẹrẹ iṣẹ pẹlu wọn. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61202610 |
3politics
| Prince Philip: Ó lo ọdún 93, lọ sí orílẹ̀-èdè 143, ó ní gbajúgbajà ìyàwò kan | Duke ilu Edinburgh, ọkọ to gbajumọ julọ ni agbaye, ti ku ni ẹni ọdun mọkandinlọgọrun Aadọrin ọdun lo fi gbe igbeaye rẹ ni abẹ idari iyawo rẹ, Ọbabinrin Elisabẹti II - ṣugbọn iru eeyan to jẹ fihan pe ko kan ni i jẹ ọkọ lasan. Nitori naa, ta ani ọkunrin to duro ti Ọbabinrin naa, ati pe bawo lo ṣe ri Ọbabinrin fẹ ni iyawo? Nkan akọkọ: Duke, ti a tun mọ si Arẹmọ Philip, ko si lara awọn ti ipo ọba tọ si - ọmọ rẹ ọkunrin lo wa ni ipo yii - nitori naa ni ko ṣe ni orukọ oye 'ọba'. Idi ni pe ni ilẹ UK, obinrin to ba fẹ ọkọ ninu ile ọba, le lo orukọ oye 'Ọbabinrin', ṣugbọn awọn ọkunrin to ba fẹ Ọbabinrin ko le pe ara awọn ni ọba. Awọn ọmọkunrin ile ọba nikan lo le ṣe bẹ ẹ. Ọmọ mẹrin ni Ọbabinrin ati Arẹmọ Philip bi: Arẹmọ Charles(72), Ọmọọbabinrin Anne (70), Arẹmọ Andrew (61), ati Arẹmọ Edward (57). Gẹgẹ bi awọn ọmọ wọn ṣe sọ, Philip ma n paṣẹ nigba ti wọn wa ni kekere. Ayaworan laafin ọba, Ingrid Seward sọ pe Arẹmọ Andrew ti sọ ọ ri pe "Ọbabinrin lo ni aanu l'oju ju, amọ baba wọn 'Philip' lo ni ibawi lọwọ. Bakan naa ni Andrew tun ṣe iranti bi baba rẹ ṣe ma n pa aalọ fun wọn ni alẹ, to si tun ma n tẹti si awọn ọmọ rẹ ti wọn ba n ka iwe Rudyard Kipling, Just So Sories. Arẹmọ Philip dagba debi i pe ọmọ-ọmọ rẹ kẹjọ dagba l'oju rẹ, o si tun ri ọmọ-ọmọ-ọmọ rẹ kẹwaa. Ọdun 1922 ni irinajo Philip bẹrẹ ni Aafin to wa ni Burkingham. Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa, ọdun 1921 ni wọn bi ni erekusu Greek, Corfu. Oun si ni abigbẹyin ati ọkunrin kan ṣoṣo ti Arẹmọ Andrew ti Greece ati Ọmọọbabinrin Alice ti Battenberg, bi. Idile to ti jade mu ki o di Arẹmọ Greece ati Denmark. Amọ ni ọdun to tẹle ibi rẹ, wọn le ẹnbi rẹ kuro ni Greece lẹyin iditẹ gbajọba kan. Ọkọ oju omi ijagun ti orilẹ-ede Britain lo gbe wọn de Italy ni alaafia, pẹlu Philip to jẹ ikoko, to n sun ninu apẹrẹ kan. Oriṣiri adanu ati òfò lo ṣẹlẹ nigb ati Philip wa ni kekere. Ni ọdun 1930, nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹjọ, iya rẹ di eero ileewosan alarun ọpọlọ. Ẹkọọkan si ni Philip n ri awọn obi rẹ mejeeji lẹyin igba naa. Baba rẹ sọ French Riviera di ile pẹlu aale rẹ kan, awọn ẹbi iya rẹ ni UK si lo tọ ọ dagba. Orukọ ẹbi naa, Mountbatten si lo pada n jẹ. Ileewe Gordonstoun, ti Scotland, lo lọ. Ileewe naa lo si ti kọ ẹkọ nipa bi eeyan ṣe n da a duro. Lọdun 1937, ọkan lara awọn ẹgbọn Philip, Cecilie, ku ninu ijamba ọkọ ofurufu pẹlu ọkọ rẹ, ọmọ orilẹ-ede Germany, iya ọkọ rẹ, ati ọmọ rẹ mejeeji. Inu oyun paapaa lo wa ni asiko naa. Ko pẹ ti Cecilie darapọ mọ ẹgbẹ Nazi, to n dari eyi to pọju ninu ijọba Germany, ni iṣẹlẹ yii waye. Pẹlu ibanujẹ ni Philip, ẹni ọdun mẹrindinlogun fi n rin tẹle posi ẹgbọn rẹ ni igboro Darmstadt. Nigba ti Philip kuro ni ileewe, diẹ lo ku ki ogun ṣẹlẹ laarin Britain ati Germany. O darapọ mọ Britannia Royal Naval College ni Dartmouth (ileewe ikọṣẹ ọmọ ogun ori omi ti UK). Nibẹ si lo ti leke awsn ti wọn jọ wa ni kilaasi. Nigba ti Ọba George VI ṣe abẹwo ẹnu iṣẹ si ileewe naa lọdun 1939, Philip lodari eto dida awọn ọmọ ọbabirnin kekeeke naa, Elizabeth ati Margaret, lara ya. Alamojuto awọn ọmọọbabinrin naa, Marian Crawford sọ pe Philip fakọyọ pupọ. Ihuwasi rẹ si dun mọ Elizabeth to jẹ ọmọ ọdun mẹtala lori. Ipa kekere kọ ni Philip ko lasiko ogun agbaye keji. Nigba ti yoo fi di ọdun 1942, to ti pe ẹni ọdun mọkanlelogun, Philip ti di ọkan lara awọn ọgagun ori omi to kere julọ. Lẹta kikọ si ni ọmọọbabinrin naa ati ọgagun fi n ba ara wọn sọrọ. Lẹyin abẹwo kan ti Philip ṣe si aafin ni asiko ọdun Keresimesi lọdun 1943, aworan rẹ ni Elizabeth gbe si ori tabili niyaara rẹ. Botilẹ jẹ pe ero diẹ lara awọn amugbalẹgbẹ Elizabeth n sọ oriṣiriṣi nkan nipa Philip ( kii ṣe eniyan jẹẹjẹ, onigberaga, ẹni ti ko kae, ti ko si nii jẹ olootọ), ifẹ ti ọmọọbabinrin ni i si ko dinku. Ọba George pada fọwọsi igbeyawo wọn, amọ awọn atunṣe kan gbọdọ waye. Arẹmọ orilẹ-ede Greece ati Denmark ọhun di ọmọ ilu ni Britain, o darapọ mọ Church of England, o si pa gbogbo oye to ni nilẹ okeere ti. Lọjọ ayẹyẹ igbeyawo rẹ ni ogunjọ oṣu Kọkanla, ọdun 1947, wọn sọ ọ di Duke ilu Edinburgh, orukọ to jẹ titi di opin ay erẹ. Ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn ni, iyawo rẹ si jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun. Igbeyawo wọn ko ti i ju ọdun mẹrin lọ, pẹlu ọmọ meji, nigba ti iṣẹ ìlú bẹrẹ. Orilẹ-ede Kenya ni wọn wa, lẹnu irinajo si awọn orilẹ-ede Commonwealth, ti iroyin iku baba Elisabẹti, Ọba George VI fi ba wọn. Ẹni ọdun mẹrindinlọgọta lo kú. Ọgagun Michael Parker, ọrẹ Duke ti Edinburgh, to tun jẹ akọwe ikọkọ fun sọ nipa asiko ti Philip gbọ pe iywao rẹ ti di Ọbabinrin. "O n wo bi ẹni ti wọn gbe ilaji ẹru gbogbo aye le lori. Aanu eeyan ko ṣe mi bẹẹ ri. O n mi soke-silẹ bi ẹni ti ipaya mu. O ri loju ẹsẹ pe asiko idakọnkọ oun ati Elisabẹti ti dopin. Opin de ba afojusun Philip gẹgẹ bi ọmọ ologun ori omi, nitori pe Ọbabinrin tuntun yoo nilo ọkọ rẹ. O di oludamọran ati alabarin fun iyawo rẹ, ojuṣe rẹ si ni lati ma a ṣe atilẹyin fun. Wahala nla ṣẹlẹ ni nkan bi ọdun 1950, nigba ti Philip fẹ ki idile ọba o ma a jẹ orukọ ẹbi rẹ, Mountbatten. "Emi nikan ni ọkunrin ti wọn ko faaye gba ni orilẹ-ede yii, lati fi orukọ rẹ sọ awọn ọmọ rẹ!" Bayi lo ṣe fi ibinu sọrọ nigba ti wọn rọ Ọbabinrin lati ṣi ma a jẹ Windsor. "Mi o yatọ si amoeba." Philip tiraka lati jẹ ṣe awọn ojuṣe ti wọn la kalẹ fun. Ṣugbọn, gẹgẹ bi iru eeyan to jẹ, o pinnu lati fẹ afẹfẹ to yatọ ni aafin ni Buckingham. Duke ko gbagbe orisin rẹ ni Greece, o si gbagbọ pe awọn ọmọ idile ọba gbọdọ ni ifarada. O ṣe idasilẹ eto ti yoo mu ki Ọbabinrin le ba awsn eeyan pade, ;ai fi iru eeyan ti wọn jẹ ṣe. Awọn ọmọ ọdọ ni aafin dẹkun fifi atike kun irun wọn. Nigba to tun gbọ pe ile ìdáná mii wa ti wọn ti n dana ounjẹ idile ọba, o ti ẹyọkan pa. Diẹ lara awọn ayipada to ṣe niṣee pẹlu bi igba ewe rẹ ṣe ri. Philip ṣeto bi tẹliffonu ṣe wa ninu aafin, ki awọn ọmọ ọdọ o ma ba ma a damu wa jiṣẹ fun Ọbabinrin. Fun'ra rẹ lo n gbe ẹrù rẹ. Oun lo si ma n se ounjẹ aarọ rẹ ninu yaara rẹ titi di asiko ti Ọbabinrin yari nitori oorun. Gẹgẹ bi oludamọran to pẹ julọ ninu itan Britain, oun fun'ra rẹ da ṣe iṣẹ bi i 22,191. Nigba to fẹhinti lẹnu iṣẹ aafin lọdun 2017, awọn ajọ ati ẹgbẹ to le ni 780 lo sọ ọ di baba'salẹ, ọmọ ẹgbẹ tabi aarẹ wọn. Orilẹ-ede 143 lo lọ l'ẹnu iṣẹ, to si ma n lo ede French ati German to gbọ. Amọ, ọkan lara awọn nkan iranti nipa rẹ ni idasilẹ ami ẹyẹ Duke ti Edinburgh, lati ọws ọga ileewe rẹ tlẹlẹ, Kurt Hahn. Awọn olukopa fun ami ẹyẹ naa (ọmọ ọdun 14 si 25) le gba ami ẹyẹ nipa ṣiṣe iṣẹ iranlọwọ, kikọ nipa ere idaray, iṣẹ ọwọ, tabi gigun apata to ga atbi irinajo ori omi. Lọdun 2016, ọdọ bi i 1.3 miliọnu lo kopa ninu eto naa lati orilẹ-ede 130. Ẹni to fẹran ere idaraya ni Philip. O si jẹ ọkan lara eeyan mẹrin to n gbegba oroke ninu ere idaraya Polo ni Uk ni nkan bi ọdun 1960. Bakan naa lo ma n polongo fun dida ẹmi awọn ẹranko igbo si. Ninu ọrọ to sọ lati ṣapejuwe ipa to ko ninu itan Britain, Philip sọ pe "Mo ti ṣe eyi ti mo lero pe o dara. "Awọn eeyan kan gba pe o dara, awọn miran si gba pe ko dara to. Ṣugbọn, kinni mo le ṣe? Mi o le yi bi mo ṣe n ṣe nkan pada. O ti mọ mi lara. Amọ, wọn o gba bẹ ẹ ni." Philip gbagbọ pe ipamọra ti Ọbabinrin ni lo mu ki ibagbepọ wọn o pẹ, amọ awọn kan ninu ile ọba sọ pe ẹẹrin lo so wọn pọ. | Prince Philip: Ó lo ọdún 93, lọ sí orílẹ̀-èdè 143, ó ní gbajúgbajà ìyàwò kan Duke ilu Edinburgh, ọkọ to gbajumọ julọ ni agbaye, ti ku ni ẹni ọdun mọkandinlọgọrun Aadọrin ọdun lo fi gbe igbeaye rẹ ni abẹ idari iyawo rẹ, Ọbabinrin Elisabẹti II - ṣugbọn iru eeyan to jẹ fihan pe ko kan ni i jẹ ọkọ lasan. Nitori naa, ta ani ọkunrin to duro ti Ọbabinrin naa, ati pe bawo lo ṣe ri Ọbabinrin fẹ ni iyawo? Nkan akọkọ: Duke, ti a tun mọ si Arẹmọ Philip, ko si lara awọn ti ipo ọba tọ si - ọmọ rẹ ọkunrin lo wa ni ipo yii - nitori naa ni ko ṣe ni orukọ oye 'ọba'. Idi ni pe ni ilẹ UK, obinrin to ba fẹ ọkọ ninu ile ọba, le lo orukọ oye 'Ọbabinrin', ṣugbọn awọn ọkunrin to ba fẹ Ọbabinrin ko le pe ara awọn ni ọba. Awọn ọmọkunrin ile ọba nikan lo le ṣe bẹ ẹ. Ọmọ mẹrin ni Ọbabinrin ati Arẹmọ Philip bi: Arẹmọ Charles(72), Ọmọọbabinrin Anne (70), Arẹmọ Andrew (61), ati Arẹmọ Edward (57). Gẹgẹ bi awọn ọmọ wọn ṣe sọ, Philip ma n paṣẹ nigba ti wọn wa ni kekere. Ayaworan laafin ọba, Ingrid Seward sọ pe Arẹmọ Andrew ti sọ ọ ri pe "Ọbabinrin lo ni aanu l'oju ju, amọ baba wọn 'Philip' lo ni ibawi lọwọ. Bakan naa ni Andrew tun ṣe iranti bi baba rẹ ṣe ma n pa aalọ fun wọn ni alẹ, to si tun ma n tẹti si awọn ọmọ rẹ ti wọn ba n ka iwe Rudyard Kipling, Just So Sories. Arẹmọ Philip dagba debi i pe ọmọ-ọmọ rẹ kẹjọ dagba l'oju rẹ, o si tun ri ọmọ-ọmọ-ọmọ rẹ kẹwaa. Ọdun 1922 ni irinajo Philip bẹrẹ ni Aafin to wa ni Burkingham. Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa, ọdun 1921 ni wọn bi ni erekusu Greek, Corfu. Oun si ni abigbẹyin ati ọkunrin kan ṣoṣo ti Arẹmọ Andrew ti Greece ati Ọmọọbabinrin Alice ti Battenberg, bi. Idile to ti jade mu ki o di Arẹmọ Greece ati Denmark. Amọ ni ọdun to tẹle ibi rẹ, wọn le ẹnbi rẹ kuro ni Greece lẹyin iditẹ gbajọba kan. Ọkọ oju omi ijagun ti orilẹ-ede Britain lo gbe wọn de Italy ni alaafia, pẹlu Philip to jẹ ikoko, to n sun ninu apẹrẹ kan. Oriṣiri adanu ati òfò lo ṣẹlẹ nigb ati Philip wa ni kekere. Ni ọdun 1930, nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹjọ, iya rẹ di eero ileewosan alarun ọpọlọ. Ẹkọọkan si ni Philip n ri awọn obi rẹ mejeeji lẹyin igba naa. Baba rẹ sọ French Riviera di ile pẹlu aale rẹ kan, awọn ẹbi iya rẹ ni UK si lo tọ ọ dagba. Orukọ ẹbi naa, Mountbatten si lo pada n jẹ. Ileewe Gordonstoun, ti Scotland, lo lọ. Ileewe naa lo si ti kọ ẹkọ nipa bi eeyan ṣe n da a duro. Lọdun 1937, ọkan lara awọn ẹgbọn Philip, Cecilie, ku ninu ijamba ọkọ ofurufu pẹlu ọkọ rẹ, ọmọ orilẹ-ede Germany, iya ọkọ rẹ, ati ọmọ rẹ mejeeji. Inu oyun paapaa lo wa ni asiko naa. Ko pẹ ti Cecilie darapọ mọ ẹgbẹ Nazi, to n dari eyi to pọju ninu ijọba Germany, ni iṣẹlẹ yii waye. Pẹlu ibanujẹ ni Philip, ẹni ọdun mẹrindinlogun fi n rin tẹle posi ẹgbọn rẹ ni igboro Darmstadt. Nigba ti Philip kuro ni ileewe, diẹ lo ku ki ogun ṣẹlẹ laarin Britain ati Germany. O darapọ mọ Britannia Royal Naval College ni Dartmouth (ileewe ikọṣẹ ọmọ ogun ori omi ti UK). Nibẹ si lo ti leke awsn ti wọn jọ wa ni kilaasi. Nigba ti Ọba George VI ṣe abẹwo ẹnu iṣẹ si ileewe naa lọdun 1939, Philip lodari eto dida awọn ọmọ ọbabirnin kekeeke naa, Elizabeth ati Margaret, lara ya. Alamojuto awọn ọmọọbabinrin naa, Marian Crawford sọ pe Philip fakọyọ pupọ. Ihuwasi rẹ si dun mọ Elizabeth to jẹ ọmọ ọdun mẹtala lori. Ipa kekere kọ ni Philip ko lasiko ogun agbaye keji. Nigba ti yoo fi di ọdun 1942, to ti pe ẹni ọdun mọkanlelogun, Philip ti di ọkan lara awọn ọgagun ori omi to kere julọ. Lẹta kikọ si ni ọmọọbabinrin naa ati ọgagun fi n ba ara wọn sọrọ. Lẹyin abẹwo kan ti Philip ṣe si aafin ni asiko ọdun Keresimesi lọdun 1943, aworan rẹ ni Elizabeth gbe si ori tabili niyaara rẹ. Botilẹ jẹ pe ero diẹ lara awọn amugbalẹgbẹ Elizabeth n sọ oriṣiriṣi nkan nipa Philip ( kii ṣe eniyan jẹẹjẹ, onigberaga, ẹni ti ko kae, ti ko si nii jẹ olootọ), ifẹ ti ọmọọbabinrin ni i si ko dinku. Ọba George pada fọwọsi igbeyawo wọn, amọ awọn atunṣe kan gbọdọ waye. Arẹmọ orilẹ-ede Greece ati Denmark ọhun di ọmọ ilu ni Britain, o darapọ mọ Church of England, o si pa gbogbo oye to ni nilẹ okeere ti. Lọjọ ayẹyẹ igbeyawo rẹ ni ogunjọ oṣu Kọkanla, ọdun 1947, wọn sọ ọ di Duke ilu Edinburgh, orukọ to jẹ titi di opin ay erẹ. Ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn ni, iyawo rẹ si jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun. Igbeyawo wọn ko ti i ju ọdun mẹrin lọ, pẹlu ọmọ meji, nigba ti iṣẹ ìlú bẹrẹ. Orilẹ-ede Kenya ni wọn wa, lẹnu irinajo si awọn orilẹ-ede Commonwealth, ti iroyin iku baba Elisabẹti, Ọba George VI fi ba wọn. Ẹni ọdun mẹrindinlọgọta lo kú. Ọgagun Michael Parker, ọrẹ Duke ti Edinburgh, to tun jẹ akọwe ikọkọ fun sọ nipa asiko ti Philip gbọ pe iywao rẹ ti di Ọbabinrin. "O n wo bi ẹni ti wọn gbe ilaji ẹru gbogbo aye le lori. Aanu eeyan ko ṣe mi bẹẹ ri. O n mi soke-silẹ bi ẹni ti ipaya mu. O ri loju ẹsẹ pe asiko idakọnkọ oun ati Elisabẹti ti dopin. Opin de ba afojusun Philip gẹgẹ bi ọmọ ologun ori omi, nitori pe Ọbabinrin tuntun yoo nilo ọkọ rẹ. O di oludamọran ati alabarin fun iyawo rẹ, ojuṣe rẹ si ni lati ma a ṣe atilẹyin fun. Wahala nla ṣẹlẹ ni nkan bi ọdun 1950, nigba ti Philip fẹ ki idile ọba o ma a jẹ orukọ ẹbi rẹ, Mountbatten. "Emi nikan ni ọkunrin ti wọn ko faaye gba ni orilẹ-ede yii, lati fi orukọ rẹ sọ awọn ọmọ rẹ!" Bayi lo ṣe fi ibinu sọrọ nigba ti wọn rọ Ọbabinrin lati ṣi ma a jẹ Windsor. "Mi o yatọ si amoeba." Philip tiraka lati jẹ ṣe awọn ojuṣe ti wọn la kalẹ fun. Ṣugbọn, gẹgẹ bi iru eeyan to jẹ, o pinnu lati fẹ afẹfẹ to yatọ ni aafin ni Buckingham. Duke ko gbagbe orisin rẹ ni Greece, o si gbagbọ pe awọn ọmọ idile ọba gbọdọ ni ifarada. O ṣe idasilẹ eto ti yoo mu ki Ọbabinrin le ba awsn eeyan pade, ;ai fi iru eeyan ti wọn jẹ ṣe. Awọn ọmọ ọdọ ni aafin dẹkun fifi atike kun irun wọn. Nigba to tun gbọ pe ile ìdáná mii wa ti wọn ti n dana ounjẹ idile ọba, o ti ẹyọkan pa. Diẹ lara awọn ayipada to ṣe niṣee pẹlu bi igba ewe rẹ ṣe ri. Philip ṣeto bi tẹliffonu ṣe wa ninu aafin, ki awọn ọmọ ọdọ o ma ba ma a damu wa jiṣẹ fun Ọbabinrin. Fun'ra rẹ lo n gbe ẹrù rẹ. Oun lo si ma n se ounjẹ aarọ rẹ ninu yaara rẹ titi di asiko ti Ọbabinrin yari nitori oorun. Gẹgẹ bi oludamọran to pẹ julọ ninu itan Britain, oun fun'ra rẹ da ṣe iṣẹ bi i 22,191. Nigba to fẹhinti lẹnu iṣẹ aafin lọdun 2017, awọn ajọ ati ẹgbẹ to le ni 780 lo sọ ọ di baba'salẹ, ọmọ ẹgbẹ tabi aarẹ wọn. Orilẹ-ede 143 lo lọ l'ẹnu iṣẹ, to si ma n lo ede French ati German to gbọ. Amọ, ọkan lara awọn nkan iranti nipa rẹ ni idasilẹ ami ẹyẹ Duke ti Edinburgh, lati ọws ọga ileewe rẹ tlẹlẹ, Kurt Hahn. Awọn olukopa fun ami ẹyẹ naa (ọmọ ọdun 14 si 25) le gba ami ẹyẹ nipa ṣiṣe iṣẹ iranlọwọ, kikọ nipa ere idaray, iṣẹ ọwọ, tabi gigun apata to ga atbi irinajo ori omi. Lọdun 2016, ọdọ bi i 1.3 miliọnu lo kopa ninu eto naa lati orilẹ-ede 130. Ẹni to fẹran ere idaraya ni Philip. O si jẹ ọkan lara eeyan mẹrin to n gbegba oroke ninu ere idaraya Polo ni Uk ni nkan bi ọdun 1960. Bakan naa lo ma n polongo fun dida ẹmi awọn ẹranko igbo si. Ninu ọrọ to sọ lati ṣapejuwe ipa to ko ninu itan Britain, Philip sọ pe "Mo ti ṣe eyi ti mo lero pe o dara. "Awọn eeyan kan gba pe o dara, awọn miran si gba pe ko dara to. Ṣugbọn, kinni mo le ṣe? Mi o le yi bi mo ṣe n ṣe nkan pada. O ti mọ mi lara. Amọ, wọn o gba bẹ ẹ ni." Philip gbagbọ pe ipamọra ti Ọbabinrin ni lo mu ki ibagbepọ wọn o pẹ, amọ awọn kan ninu ile ọba sọ pe ẹẹrin lo so wọn pọ. | https://www.bbc.com/yoruba/56694791 |
4religion
| Deborah Samuel: Gani Adams tutọ́ sókè fojú gbàá lórí ìtàjẹ̀sílẹ̀ arábìnrin Deborah ní Sokoto, ohun tó sọ rèé | Aarẹ Ọna Kakanfo Ilẹ Yoruba patapata Iba Gani Adams ti dasi ọrọ iṣekupani arabinrin Deborah Samuel toi waye ni ipinlẹ Sokoto. Gani Adams sọ pe awọn to ṣeku pa arabinrin naa n gbero lati da ogun ẹlẹyamẹya ati ẹlẹsinmẹsin silẹ ni ilẹ Yoruba ni. O fi ọrọ yi sita gba tọwọ agbẹnusọ rẹ Kehinde Aderemi lọjọ Aiku to kọja yi. Adájọ́ 34 táa tán nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé Ninu atẹjade naa, Iba Adams ni ''ọrọ ti doju rẹ bayi ni Naijiria ati pe ti wọn ko ba wa nkan ṣe si, o le di wahala ti ipa ko ni le ka'' O kilọ pe agbegbe awọn ti gburo pe awọn alaburu kan ti n wọle si ilẹ Yoruba pẹlu erongba ki wọn dana sun ilẹ Yoruba. O ni awọn ko ni faaye gba ipete peero wọn nitori o ṣeeṣe ki o da wahala ẹlẹsin ati ẹlẹyamẹya silẹ laarin awọn eeyan. ''Awọn alakatakiti ẹsin yi ni ibi ti wọn fọkan si.Ireti wọn si ni pe ki wọn da wahala silẹ ni apa iwọ oorun Guusu wa, ṣugbọn a ko ni faaye gba wọn'' O bẹnu atẹ lu isọwọ bi wọn ṣe pa arabinrin Deborah Samuel ni ipakupa to si ni awọn agbofinro tete mu awọn to wa nidi iku rẹ ki wọn si foju wina ofin ni kiakia. Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba sọ pe ko pẹ yi lawọn agbarijọpọ eleto aabo ni Ilẹ Yoruba lọgun sita lori bi awọn ajoji ti kii ṣe ọmọ Naijiria ṣe yawọ ilẹ Yoruba. O ni awọn ke gbajare nitori pupọ awọn wọnyi lo maa n gbe ọbẹ ati nkan ija oloro mii rin kaakiri ati pe wọn ṣetan lati ṣaburu fawọn eeyan. O tẹnu mọ pe iṣẹlẹ iṣekupani Deborah yi ṣafihan aibikita awọn alakatakiti yi. ''Wọn dawọ jọ na, wọn ṣe leṣe,wọn lu debi iku wọn si dana sun lalae kaanu rẹ''Iba Adams wa parọwa si Gomina ipinlẹ Sokoto Aminu Waziri Tambuwal lati daabo bo gbogbo araalu. O ni ko ṣa gbogbo ipa rẹ lati ri pe ọwọ tẹ awọn to wa nidi iṣẹlẹ yi to fi mọ awọn alatilẹyin wọn. ''Ofin wa nilẹ yi to fidi idaabo araalu kọọkan mulẹ a si gbọdọ bọwọ fun iru ofin yi.Ẹnikẹni to ba tako ofin yi gbọdọ foju wina ofin ni'' | Deborah Samuel: Gani Adams tutọ́ sókè fojú gbàá lórí ìtàjẹ̀sílẹ̀ arábìnrin Deborah ní Sokoto, ohun tó sọ rèé Aarẹ Ọna Kakanfo Ilẹ Yoruba patapata Iba Gani Adams ti dasi ọrọ iṣekupani arabinrin Deborah Samuel toi waye ni ipinlẹ Sokoto. Gani Adams sọ pe awọn to ṣeku pa arabinrin naa n gbero lati da ogun ẹlẹyamẹya ati ẹlẹsinmẹsin silẹ ni ilẹ Yoruba ni. O fi ọrọ yi sita gba tọwọ agbẹnusọ rẹ Kehinde Aderemi lọjọ Aiku to kọja yi. Adájọ́ 34 táa tán nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé Ninu atẹjade naa, Iba Adams ni ''ọrọ ti doju rẹ bayi ni Naijiria ati pe ti wọn ko ba wa nkan ṣe si, o le di wahala ti ipa ko ni le ka'' O kilọ pe agbegbe awọn ti gburo pe awọn alaburu kan ti n wọle si ilẹ Yoruba pẹlu erongba ki wọn dana sun ilẹ Yoruba. O ni awọn ko ni faaye gba ipete peero wọn nitori o ṣeeṣe ki o da wahala ẹlẹsin ati ẹlẹyamẹya silẹ laarin awọn eeyan. ''Awọn alakatakiti ẹsin yi ni ibi ti wọn fọkan si.Ireti wọn si ni pe ki wọn da wahala silẹ ni apa iwọ oorun Guusu wa, ṣugbọn a ko ni faaye gba wọn'' O bẹnu atẹ lu isọwọ bi wọn ṣe pa arabinrin Deborah Samuel ni ipakupa to si ni awọn agbofinro tete mu awọn to wa nidi iku rẹ ki wọn si foju wina ofin ni kiakia. Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba sọ pe ko pẹ yi lawọn agbarijọpọ eleto aabo ni Ilẹ Yoruba lọgun sita lori bi awọn ajoji ti kii ṣe ọmọ Naijiria ṣe yawọ ilẹ Yoruba. O ni awọn ke gbajare nitori pupọ awọn wọnyi lo maa n gbe ọbẹ ati nkan ija oloro mii rin kaakiri ati pe wọn ṣetan lati ṣaburu fawọn eeyan. O tẹnu mọ pe iṣẹlẹ iṣekupani Deborah yi ṣafihan aibikita awọn alakatakiti yi. ''Wọn dawọ jọ na, wọn ṣe leṣe,wọn lu debi iku wọn si dana sun lalae kaanu rẹ''Iba Adams wa parọwa si Gomina ipinlẹ Sokoto Aminu Waziri Tambuwal lati daabo bo gbogbo araalu. O ni ko ṣa gbogbo ipa rẹ lati ri pe ọwọ tẹ awọn to wa nidi iṣẹlẹ yi to fi mọ awọn alatilẹyin wọn. ''Ofin wa nilẹ yi to fidi idaabo araalu kọọkan mulẹ a si gbọdọ bọwọ fun iru ofin yi.Ẹnikẹni to ba tako ofin yi gbọdọ foju wina ofin ni'' | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61463529 |
3politics
| Makinde: Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní àwọn kò padà lẹ́yìn Seyi Makinde, gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ | Ọrọ Ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC nipinlẹ Ọyọ ti di ti ologbo ati eku bayii paapaa julọ lori ọrọ gomina Ṣeyi Makinde ati iṣejọba rẹ nipinlẹ naa. Laipẹ yii ni iroyin jade pe ẹgbẹ oṣelu APC n pariwo sita pe iṣejọba gomina naa ko ba awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu rẹ, iyẹn PDP lara mu, wọn si ti n kọ ẹyin wọn sii lọkọọkan ejeeji. Haa-hin in ni iroyin naa ṣe ọpọ onwoye nitori pe ko si ẹni lee ro pe ẹgbẹ kan to wa lori alefaa lee kẹyin si aṣoju wọn ninu iṣejọba. Amọṣa, ẹgbẹ oṣelu PDP ti ni ko si nnkan to jọọ rara ni nitori pe ọmọ ẹnii kii ṣe idi bẹbẹrẹ ka fi ilẹẹkẹ sidi ọmọ ẹlomiran. Atẹjade kan ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi sita eyi ti alukoro rẹ, Akeem Ọlatunji fi ọwọ si ṣalaye pe ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ kan Ọ̀Rọ̀ n tun irọ ta faraalu ni. O ni gbagbagba lawọn aṣiwaju ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP wa lẹyin Gomina Makinde atipe iṣọkan to jina denu lo wa laarin ẹgbẹ oṣelu naa. | Makinde: Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní àwọn kò padà lẹ́yìn Seyi Makinde, gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ọrọ Ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC nipinlẹ Ọyọ ti di ti ologbo ati eku bayii paapaa julọ lori ọrọ gomina Ṣeyi Makinde ati iṣejọba rẹ nipinlẹ naa. Laipẹ yii ni iroyin jade pe ẹgbẹ oṣelu APC n pariwo sita pe iṣejọba gomina naa ko ba awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu rẹ, iyẹn PDP lara mu, wọn si ti n kọ ẹyin wọn sii lọkọọkan ejeeji. Haa-hin in ni iroyin naa ṣe ọpọ onwoye nitori pe ko si ẹni lee ro pe ẹgbẹ kan to wa lori alefaa lee kẹyin si aṣoju wọn ninu iṣejọba. Amọṣa, ẹgbẹ oṣelu PDP ti ni ko si nnkan to jọọ rara ni nitori pe ọmọ ẹnii kii ṣe idi bẹbẹrẹ ka fi ilẹẹkẹ sidi ọmọ ẹlomiran. Atẹjade kan ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi sita eyi ti alukoro rẹ, Akeem Ọlatunji fi ọwọ si ṣalaye pe ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ kan Ọ̀Rọ̀ n tun irọ ta faraalu ni. O ni gbagbagba lawọn aṣiwaju ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP wa lẹyin Gomina Makinde atipe iṣọkan to jina denu lo wa laarin ẹgbẹ oṣelu naa. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49627704 |
4religion
| Church of Satan: Báwo ni ìjọ́sìn ṣe n rí nínú ìjọ Sátánì? | Laipẹ yii ni ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ Naijiria, to wa ni ilu Umuahia nipinlẹ Abia, gba oniduro oludasilẹ ijọ Satani, Ifekwe Udo. Oun ati awọn mẹtadinlogun miran, ni awọn ọlọpaa mu nitori ija igboro to waye ni Ebem Ohafia. Awọn ara ilu naa fi ẹsun kan Udo ati ijọ rẹ pe, apẹẹrẹ buruku ni wọn jẹ fun ilu naa, ti wọn si ba awọn dukia ijọ naa jẹ. Lara ẹsun ti awọn araalu tun fi kan an ni pe, o n da alaafia ilu naa ru. Koda, ijọba ibilẹ naa ti sọ pe ko tun gbọdọ ko ijọ rẹ jọ mọ ni ilu naa, nitori pe o n ta epo si aṣọ àlà ilu naa. Ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 1966 ni wọn da ijọ Satani silẹ, lati ọwọ Anton Szandor LaVey, nilu San Francisco l'orilẹ-ede America. Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ni itakun agbaye ṣọọṣi naa, oun ni ipejọpọ akọkọ to n gbe igbe aye rẹ gẹgẹ bi ẹlẹran ara. Fun awọn olujọsin, wọn ko sin Satani, ṣugbọn wọn ri i gẹgẹ bi apẹẹrẹ to ba iru eeyan ti wọn jẹ mu nipa ìbí. Wọn sọ pe esu duro gẹgẹ bi awokọṣe fun igberaga, ominira, ati gbigbe igbe aye ẹni lọna to wu ni - awọn amuyẹ ti awọn kan n pe ni iwa buburu. Igbagbọ awọn ọmọ ijọ Satani ni pe eniyan, nipa ọgbọn inu rẹ, lo da gbogbo awọn ọlọrun ke ke ke. Ẹnikẹni to n sin iru awọn ọlọrun bẹ ẹ, ẹni to da a ni wọn n sin. Ko tan sibẹ o, awọn ọmọ ijọ Satani sọ pe awọn ni ọlọrun ara wọn. Ati pe awọn n fi ifẹ han si ẹni to ba tọ si, ati ibinu si ẹni to ba mu inu bi wọn, tabi tapa si igbagbọ wọn. LaVey gbagbọ pe, Ọlọrun awọn Kristiẹni ko ni òye tabi ni imọ nipa bi ko ṣe rọrun lati jẹ eniyan ẹlẹran ara. O si pinnu lati fi opin si "iye rira, ati abosi, ti awọn ṣọọṣi ẹsin Kristiẹni n polongo". Ati nnkan ti yoo mu ki awọn eeyan ni ominira lati lo agbara okunkun fun ifẹ ara wọn. Oriṣa kan to si farajọ iru nkan to fẹ ni Satani - "ẹda to n fun ni ni èrè to yẹ. Ẹni to jẹ pe dipo ki o dá ẹṣẹ, ki ẹri ọkan o le ma a jẹ awọn eeyan, o kuku fi aaye gba titẹ ifẹ ara ẹni lọrun. Oun nikan ni oriṣa ti ọrọ wa ye." Ibẹrẹ ijọ Satani: Lati nkan bi ọdun 1950, ni awọn to faramọ erongba LaVey ti n sun mọ ọ, nipa kikorajọ pọ si ile rẹ "Black House" nilu San Francisco. Awọn iwadii ti LaVey ṣe nipa ẹmi okunkun, lo pilẹ bi wọn ṣe n lo ẹgba ọrun dudu ati pupa, to ni aworan ẹyẹ àdán. Ṣọọṣi naa tun sọ pe lẹyin ọdun diẹ, LaVey bẹrẹ si iṣẹ idán okunkun ati agbara irubọ, o n ṣe nipa igbega lẹni iṣẹ, ẹbun ọfẹ, owo, adun ibalopọ, ati pipa tabi yanju awọn ọta rẹ. Eyi lo tubọ mu ki ọpọ eeyan sun mọ, nitori wọn gbagbọ pe, o ti ni aṣẹ Agbara Okunkun Aye. Laarin ọdun kan aabọ ti wọn da ijọ Satani silẹ, ẹẹmẹta ni ariwo sọ lori rẹ ninu awọn iwe iroyin. Igba akọkọ ni ti igbeyawo to waye laarin gbajugbaja akọroyin kan, John Raymond, ati Judith Case, ọmọ gbajugbaja agbẹjọro. Awọn mejeeji lo jẹ ọmọ ijọ, ti wọn si kesi Olori Alufaa wọn, LaVey lati so wọn pọ ni orukọ Satani. Gbogbo ileeṣẹ iroyin nilẹ America, to fi de Europe lo fẹ ẹ ni aṣoju nibi eto igbeyawo naa, lati kọ nipa ara meeriri igbeyawo ọhun. Ipele àṣẹ ninu ijọ Satani: Ọmọ ijọ to f'orukọ silẹ Ọmọ ẹgbẹ to n ṣe deede (Oye Akọkọ) Ajẹ/Oṣo (Oye keji) Alufaa ọkunrin/obinrin (Oye kẹta) Magistra/Magister (Oye kẹrin) Maga/Magus(Oye Karun un) Ilana Ijọsin wọn: Irubọ wọn akọkọ jẹ iṣọtẹ si ẹsin Kristiẹni. N ṣe ni wọn sẹ pẹpẹ obinrin to wa ni ihoho, pẹlu orin ikọkukọ. Koda, wọn dori agbelebu kodo, ti wọn si ka Adura Oluwa lati ipari. 'Omi mimọ' ti wọn gbe kalẹ ni wọn sọ di aimọ, nipa kiki nkan si oju ara obinrin. Ọti wiski ni wọn fi jẹ ounjẹ alẹ Oluwa dipo ẹjẹ Jesu. Awọn orukọ oriṣa ni wọn si n pe, dipo orukọ Ọlọrun awọn Kristiẹni. Igbakeji ni asiko ti LaVey ṣe iribọmi fun ọmọ rẹ obinrin ni ilana Satani. Dipo riri ọmọ naa sinu omi, ẹnu ọna pẹpẹ ijọ ni ọmọ naa joko si, pẹlu oriṣiriṣi nkan ti ẹnu n jẹ. Bakan naa lo wọ koto to ni aworan Satani si ori, to si ka oriṣiriṣi ọrọ lati jẹjẹ atilẹyin ati ifọkansi fun Satani. Ọpọlọpọ wọn ko sin Satani: Iyalẹnu to wa nibẹ ni pe ọpọlọpọ awọn to jẹ olufọkansin ninu ijọ naa kii jọsin fun Satani - wọn ko gbagbọ ninu ọlọrun kankan. Wọn ko tako ṣiṣe ọdun Keresimesi: Iyalẹnu nla ni eyi jẹ lati ri i pe wọn faramọ ṣiṣe ajọyọ ọjọ ibi Jesu. Igbagbọ wọn nipe lọwọ awọn ẹlẹsin ibilẹ ni awọn Kristiẹni ti ja akoko ayẹyẹ naa gba. Ṣugbọn ṣa, Baba Keresi jẹ ọna lati dun ara ẹni ninu, eyi to jẹ ọkan pataki lara afojusun wọn. "Ni asiko yii, a n gbadun adun aye, a si wà pẹlu awọn ti a fẹran." O ko le ri ijọ Satani kankan ni agbegbe rẹ: Gẹgẹ bi o ṣe wa lori itakun agbaye wọn, ijọ Satani ko ni ile ijọsin kankan, nitori pe "o tako ilana ti ẹnikọọkan wa n gba lo igbeaye wa. Yatọ si ile oludasilẹ rẹ, ti wọn ti bẹrẹ ijọ naa, wọn ti fi igba kan ni awọn ẹka ile ijọsin , ṣugbọn wọn ti tu wọn ka, nigba ti wọn ro o pe ko ba oju mu. Koda, Olu ijọ naa ti kuro ni ile LaVey ni San Francisco, o si ti wa ni ilu New York. Wọn ko si fi aaye silẹ fun ẹnikẹni lati ṣe abẹwo si ibẹ. Ida kọnkọ si ni wọn ti maa n ṣe awọn ayẹyẹ wọn. Ti alejo nile rẹ ba mu inu bi ọ, huwa si i laini aanu Ma ṣe ni ibalopọ ti ẹni naa ko ba fi ami han pe, oun fẹ ẹ ba ọ lopọ Ma ṣe pa awọn ọmọde lara Ma ṣe pa ẹranko, ayafi fun ounjẹ rẹ tabi ti o ba doju ija kọ ọ Ma ṣe wa ija ẹnikẹni, ṣugbọn o le pa ẹni to ba wa ija rẹ run, lẹyin ti o ba ti kilọ fun. Awọn nkan ti wọn ka si ẹṣẹ ni jijẹ omugọ, imọ tara ẹni nikan, ki eeyan o ma a dibọn, titan ara ẹni jẹ, aini Ijọ naa tako lilo, ati katakara oogun oloro. Wọn gbagbọ pe ọmọ ijọ to ba tako ofin to de oogun oloro ni orilẹ-ede rẹ, ṣe e si iparun ara rẹ. Ijọ Satani kii ṣe fun talika: Igba ati marundinlọgbọn Dọla (N81,000) ni ọmọ ẹgbẹ tuntun ma n san lati darapọ. Eyi si da lori bi ẹni naa ba ṣe le dahun awọn ibeere ti wọn ba bi i. Igbakuugba si ni wọn le fi opin si jijẹ ọmọ ẹgbẹ fun ẹni naa. | Church of Satan: Báwo ni ìjọ́sìn ṣe n rí nínú ìjọ Sátánì? Laipẹ yii ni ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ Naijiria, to wa ni ilu Umuahia nipinlẹ Abia, gba oniduro oludasilẹ ijọ Satani, Ifekwe Udo. Oun ati awọn mẹtadinlogun miran, ni awọn ọlọpaa mu nitori ija igboro to waye ni Ebem Ohafia. Awọn ara ilu naa fi ẹsun kan Udo ati ijọ rẹ pe, apẹẹrẹ buruku ni wọn jẹ fun ilu naa, ti wọn si ba awọn dukia ijọ naa jẹ. Lara ẹsun ti awọn araalu tun fi kan an ni pe, o n da alaafia ilu naa ru. Koda, ijọba ibilẹ naa ti sọ pe ko tun gbọdọ ko ijọ rẹ jọ mọ ni ilu naa, nitori pe o n ta epo si aṣọ àlà ilu naa. Ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 1966 ni wọn da ijọ Satani silẹ, lati ọwọ Anton Szandor LaVey, nilu San Francisco l'orilẹ-ede America. Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ni itakun agbaye ṣọọṣi naa, oun ni ipejọpọ akọkọ to n gbe igbe aye rẹ gẹgẹ bi ẹlẹran ara. Fun awọn olujọsin, wọn ko sin Satani, ṣugbọn wọn ri i gẹgẹ bi apẹẹrẹ to ba iru eeyan ti wọn jẹ mu nipa ìbí. Wọn sọ pe esu duro gẹgẹ bi awokọṣe fun igberaga, ominira, ati gbigbe igbe aye ẹni lọna to wu ni - awọn amuyẹ ti awọn kan n pe ni iwa buburu. Igbagbọ awọn ọmọ ijọ Satani ni pe eniyan, nipa ọgbọn inu rẹ, lo da gbogbo awọn ọlọrun ke ke ke. Ẹnikẹni to n sin iru awọn ọlọrun bẹ ẹ, ẹni to da a ni wọn n sin. Ko tan sibẹ o, awọn ọmọ ijọ Satani sọ pe awọn ni ọlọrun ara wọn. Ati pe awọn n fi ifẹ han si ẹni to ba tọ si, ati ibinu si ẹni to ba mu inu bi wọn, tabi tapa si igbagbọ wọn. LaVey gbagbọ pe, Ọlọrun awọn Kristiẹni ko ni òye tabi ni imọ nipa bi ko ṣe rọrun lati jẹ eniyan ẹlẹran ara. O si pinnu lati fi opin si "iye rira, ati abosi, ti awọn ṣọọṣi ẹsin Kristiẹni n polongo". Ati nnkan ti yoo mu ki awọn eeyan ni ominira lati lo agbara okunkun fun ifẹ ara wọn. Oriṣa kan to si farajọ iru nkan to fẹ ni Satani - "ẹda to n fun ni ni èrè to yẹ. Ẹni to jẹ pe dipo ki o dá ẹṣẹ, ki ẹri ọkan o le ma a jẹ awọn eeyan, o kuku fi aaye gba titẹ ifẹ ara ẹni lọrun. Oun nikan ni oriṣa ti ọrọ wa ye." Ibẹrẹ ijọ Satani: Lati nkan bi ọdun 1950, ni awọn to faramọ erongba LaVey ti n sun mọ ọ, nipa kikorajọ pọ si ile rẹ "Black House" nilu San Francisco. Awọn iwadii ti LaVey ṣe nipa ẹmi okunkun, lo pilẹ bi wọn ṣe n lo ẹgba ọrun dudu ati pupa, to ni aworan ẹyẹ àdán. Ṣọọṣi naa tun sọ pe lẹyin ọdun diẹ, LaVey bẹrẹ si iṣẹ idán okunkun ati agbara irubọ, o n ṣe nipa igbega lẹni iṣẹ, ẹbun ọfẹ, owo, adun ibalopọ, ati pipa tabi yanju awọn ọta rẹ. Eyi lo tubọ mu ki ọpọ eeyan sun mọ, nitori wọn gbagbọ pe, o ti ni aṣẹ Agbara Okunkun Aye. Laarin ọdun kan aabọ ti wọn da ijọ Satani silẹ, ẹẹmẹta ni ariwo sọ lori rẹ ninu awọn iwe iroyin. Igba akọkọ ni ti igbeyawo to waye laarin gbajugbaja akọroyin kan, John Raymond, ati Judith Case, ọmọ gbajugbaja agbẹjọro. Awọn mejeeji lo jẹ ọmọ ijọ, ti wọn si kesi Olori Alufaa wọn, LaVey lati so wọn pọ ni orukọ Satani. Gbogbo ileeṣẹ iroyin nilẹ America, to fi de Europe lo fẹ ẹ ni aṣoju nibi eto igbeyawo naa, lati kọ nipa ara meeriri igbeyawo ọhun. Ipele àṣẹ ninu ijọ Satani: Ọmọ ijọ to f'orukọ silẹ Ọmọ ẹgbẹ to n ṣe deede (Oye Akọkọ) Ajẹ/Oṣo (Oye keji) Alufaa ọkunrin/obinrin (Oye kẹta) Magistra/Magister (Oye kẹrin) Maga/Magus(Oye Karun un) Ilana Ijọsin wọn: Irubọ wọn akọkọ jẹ iṣọtẹ si ẹsin Kristiẹni. N ṣe ni wọn sẹ pẹpẹ obinrin to wa ni ihoho, pẹlu orin ikọkukọ. Koda, wọn dori agbelebu kodo, ti wọn si ka Adura Oluwa lati ipari. 'Omi mimọ' ti wọn gbe kalẹ ni wọn sọ di aimọ, nipa kiki nkan si oju ara obinrin. Ọti wiski ni wọn fi jẹ ounjẹ alẹ Oluwa dipo ẹjẹ Jesu. Awọn orukọ oriṣa ni wọn si n pe, dipo orukọ Ọlọrun awọn Kristiẹni. Igbakeji ni asiko ti LaVey ṣe iribọmi fun ọmọ rẹ obinrin ni ilana Satani. Dipo riri ọmọ naa sinu omi, ẹnu ọna pẹpẹ ijọ ni ọmọ naa joko si, pẹlu oriṣiriṣi nkan ti ẹnu n jẹ. Bakan naa lo wọ koto to ni aworan Satani si ori, to si ka oriṣiriṣi ọrọ lati jẹjẹ atilẹyin ati ifọkansi fun Satani. Ọpọlọpọ wọn ko sin Satani: Iyalẹnu to wa nibẹ ni pe ọpọlọpọ awọn to jẹ olufọkansin ninu ijọ naa kii jọsin fun Satani - wọn ko gbagbọ ninu ọlọrun kankan. Wọn ko tako ṣiṣe ọdun Keresimesi: Iyalẹnu nla ni eyi jẹ lati ri i pe wọn faramọ ṣiṣe ajọyọ ọjọ ibi Jesu. Igbagbọ wọn nipe lọwọ awọn ẹlẹsin ibilẹ ni awọn Kristiẹni ti ja akoko ayẹyẹ naa gba. Ṣugbọn ṣa, Baba Keresi jẹ ọna lati dun ara ẹni ninu, eyi to jẹ ọkan pataki lara afojusun wọn. "Ni asiko yii, a n gbadun adun aye, a si wà pẹlu awọn ti a fẹran." O ko le ri ijọ Satani kankan ni agbegbe rẹ: Gẹgẹ bi o ṣe wa lori itakun agbaye wọn, ijọ Satani ko ni ile ijọsin kankan, nitori pe "o tako ilana ti ẹnikọọkan wa n gba lo igbeaye wa. Yatọ si ile oludasilẹ rẹ, ti wọn ti bẹrẹ ijọ naa, wọn ti fi igba kan ni awọn ẹka ile ijọsin , ṣugbọn wọn ti tu wọn ka, nigba ti wọn ro o pe ko ba oju mu. Koda, Olu ijọ naa ti kuro ni ile LaVey ni San Francisco, o si ti wa ni ilu New York. Wọn ko si fi aaye silẹ fun ẹnikẹni lati ṣe abẹwo si ibẹ. Ida kọnkọ si ni wọn ti maa n ṣe awọn ayẹyẹ wọn. Ti alejo nile rẹ ba mu inu bi ọ, huwa si i laini aanu Ma ṣe ni ibalopọ ti ẹni naa ko ba fi ami han pe, oun fẹ ẹ ba ọ lopọ Ma ṣe pa awọn ọmọde lara Ma ṣe pa ẹranko, ayafi fun ounjẹ rẹ tabi ti o ba doju ija kọ ọ Ma ṣe wa ija ẹnikẹni, ṣugbọn o le pa ẹni to ba wa ija rẹ run, lẹyin ti o ba ti kilọ fun. Awọn nkan ti wọn ka si ẹṣẹ ni jijẹ omugọ, imọ tara ẹni nikan, ki eeyan o ma a dibọn, titan ara ẹni jẹ, aini Ijọ naa tako lilo, ati katakara oogun oloro. Wọn gbagbọ pe ọmọ ijọ to ba tako ofin to de oogun oloro ni orilẹ-ede rẹ, ṣe e si iparun ara rẹ. Ijọ Satani kii ṣe fun talika: Igba ati marundinlọgbọn Dọla (N81,000) ni ọmọ ẹgbẹ tuntun ma n san lati darapọ. Eyi si da lori bi ẹni naa ba ṣe le dahun awọn ibeere ti wọn ba bi i. Igbakuugba si ni wọn le fi opin si jijẹ ọmọ ẹgbẹ fun ẹni naa. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-53536774 |
1entertainment
| Grammy Award: Burna, Sunny Ade, Femi Kuti ni àwọn akọrin Nàìjíríà tí orin wọ̀n gbà ìdánimọ̀ | Ọmọ ti yoo ba jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu samusamu, bẹẹ lọrọ ri fun ilumọka akọrin takasufe ọmọ Naijiria nni, Burna Boy, ẹni to ti kọrin rẹ debi idanimọ Grammy bayii. Loju opo ayelujara awọn alakoso eto ami ẹyẹ Grammy, ni wọn ti kede pe orukọ Burna Boy wa ninu akọsilẹ orukọ awọn eeyan ti wọn n woye fun ami ẹyẹ. Isọri ami ẹyẹ ti wọn si fi orukọ Burna si ni ami ẹyẹ fun orin agbaye to fakọyọ julọ (Best World Music Album), orukọ awo orin rẹ to gbayi ti wọn fi faa kalẹ ni African Giant. Ikede yii ti wa n mu ki awọn ọmọ Naijiria, akọrin ati awọn ololufẹ rẹ maa kan sara si loju opo Twitter rẹ pe o ku oriire. Awọn akọrin miran ti wọn ti fa kalẹ fami ẹyẹ Grammy ṣaaju: Angelique Kidjo lakọrin kan to ti gba ami ẹyẹ ni ipele ti wọn fa Burna Boy kalẹ fun yii. Lọdun 2016 si lo gba ami ẹyẹ naa. Bi a ba ni ki a wo awọn akọrin lorilẹede Naijiria ti wọn ti fa kalẹ fun ami yii, wọn ṣe bii ẹni pọ diẹ. Lara wọn la ti ri King Sunny Ade ti wọn fa kalẹ lẹẹmeji ọtọọtọ lọdun 1983 fun awo orin rẹ ti wọn pe ni 'Synchro System'. Bẹẹ ni wọn fa awo orin rẹ miran 'Odu' kalẹ lọdun 1998 ni isọri ami ẹyẹ ti Burna Boy n dije fun bayii. Awọn akọrin miran to tun ti kọrin gba idanimọ yii ni: | Grammy Award: Burna, Sunny Ade, Femi Kuti ni àwọn akọrin Nàìjíríà tí orin wọ̀n gbà ìdánimọ̀ Ọmọ ti yoo ba jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu samusamu, bẹẹ lọrọ ri fun ilumọka akọrin takasufe ọmọ Naijiria nni, Burna Boy, ẹni to ti kọrin rẹ debi idanimọ Grammy bayii. Loju opo ayelujara awọn alakoso eto ami ẹyẹ Grammy, ni wọn ti kede pe orukọ Burna Boy wa ninu akọsilẹ orukọ awọn eeyan ti wọn n woye fun ami ẹyẹ. Isọri ami ẹyẹ ti wọn si fi orukọ Burna si ni ami ẹyẹ fun orin agbaye to fakọyọ julọ (Best World Music Album), orukọ awo orin rẹ to gbayi ti wọn fi faa kalẹ ni African Giant. Ikede yii ti wa n mu ki awọn ọmọ Naijiria, akọrin ati awọn ololufẹ rẹ maa kan sara si loju opo Twitter rẹ pe o ku oriire. Awọn akọrin miran ti wọn ti fa kalẹ fami ẹyẹ Grammy ṣaaju: Angelique Kidjo lakọrin kan to ti gba ami ẹyẹ ni ipele ti wọn fa Burna Boy kalẹ fun yii. Lọdun 2016 si lo gba ami ẹyẹ naa. Bi a ba ni ki a wo awọn akọrin lorilẹede Naijiria ti wọn ti fa kalẹ fun ami yii, wọn ṣe bii ẹni pọ diẹ. Lara wọn la ti ri King Sunny Ade ti wọn fa kalẹ lẹẹmeji ọtọọtọ lọdun 1983 fun awo orin rẹ ti wọn pe ni 'Synchro System'. Bẹẹ ni wọn fa awo orin rẹ miran 'Odu' kalẹ lọdun 1998 ni isọri ami ẹyẹ ti Burna Boy n dije fun bayii. Awọn akọrin miran to tun ti kọrin gba idanimọ yii ni: | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-50492273 |
3politics
| Peter Obi ti borí ètò ìdìbò Ààrẹ- Kenneth Okonkwo | Ọkan lara awọn agbẹnusọ fun ìpolongo ẹgbẹ oselu Labour Party. Kenneth Okonkwo ti ogun rẹ gbari pe oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu Labour Party, ti bori eto ìdibo aarẹ lọdun 2023. Okonkwo, ẹni to jẹ gbajugbaja onitiata sísọ loju ọrọ naa nigba to kopa ninu ifọrọwerọ kan lori Channels TV. Gẹgẹ bii o ṣe sọ, o ni Gomina ana ni Ipinlẹ Anambra ti le waju awọn oludije yoku saaju eto ìdibo aarẹ. "Ani o ti bori, ẹ lọ wo iwadi ti a ti ṣe tí mo sọ fun yin, ẹ wo bi awọn eeyan ṣe dibo; esi ìdibo mẹta ti jade, ANAP, We-Together ati Bloomberg; to si bori ninu gbogbo wọn. "Laipẹ, ki ìdibo to waye, awọn oludije meji yoo sisẹ pẹlu wa, ti yoo wa ku Peter Obi ati awọn yoku. "Nitori to ba di asiko idibo, awọn oludije yii koni ni anfani lati ri ida marun un ibo, ti wọn ko ba ti rí ida marun-un, a le pe wọn ni awọn yooku." Okonkwo, ẹni to tun jẹ Agbẹjọro tẹsiwaju pe yatọ si awọn oludije miiran, Peter Obi kọ lati mu oselu mo ẹlẹyamẹya. O ni pupọ lara awọn oludije yoku lo kaakiri pẹlu oṣelu ẹlẹyamẹya sugbọn Obi da yatọ, to si n wa isọkan ati ilọsiwaju Orilẹede Naijiria. "Atiku lọ ilẹ Hausa, o ni ki wọn dibo yan ẹni to wa lati ilẹ Hausa, kí wọn si jina si awọn ẹya yooku. Àpẹẹrẹ dida ẹya si nìyẹn. "Tinubu lọ ipinlẹ Ogun, o sọ asiko Yoruba lokan ati oun lo kan. "Peter Obi lọ si ilẹ Igbo, o ni ki wọn ma dibo yan oun nitori oun jẹ igbo sugbọn nitori oun jẹ akikanju ọkùnrin ti isẹ ye. O ni ki ṣe asiko ẹnikẹni lati di aarẹ sugbọn o jẹ asiko fun awọn ọmọ orile-ede Naijiria lati yan adari wọn." | Peter Obi ti borí ètò ìdìbò Ààrẹ- Kenneth Okonkwo Ọkan lara awọn agbẹnusọ fun ìpolongo ẹgbẹ oselu Labour Party. Kenneth Okonkwo ti ogun rẹ gbari pe oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu Labour Party, ti bori eto ìdibo aarẹ lọdun 2023. Okonkwo, ẹni to jẹ gbajugbaja onitiata sísọ loju ọrọ naa nigba to kopa ninu ifọrọwerọ kan lori Channels TV. Gẹgẹ bii o ṣe sọ, o ni Gomina ana ni Ipinlẹ Anambra ti le waju awọn oludije yoku saaju eto ìdibo aarẹ. "Ani o ti bori, ẹ lọ wo iwadi ti a ti ṣe tí mo sọ fun yin, ẹ wo bi awọn eeyan ṣe dibo; esi ìdibo mẹta ti jade, ANAP, We-Together ati Bloomberg; to si bori ninu gbogbo wọn. "Laipẹ, ki ìdibo to waye, awọn oludije meji yoo sisẹ pẹlu wa, ti yoo wa ku Peter Obi ati awọn yoku. "Nitori to ba di asiko idibo, awọn oludije yii koni ni anfani lati ri ida marun un ibo, ti wọn ko ba ti rí ida marun-un, a le pe wọn ni awọn yooku." Okonkwo, ẹni to tun jẹ Agbẹjọro tẹsiwaju pe yatọ si awọn oludije miiran, Peter Obi kọ lati mu oselu mo ẹlẹyamẹya. O ni pupọ lara awọn oludije yoku lo kaakiri pẹlu oṣelu ẹlẹyamẹya sugbọn Obi da yatọ, to si n wa isọkan ati ilọsiwaju Orilẹede Naijiria. "Atiku lọ ilẹ Hausa, o ni ki wọn dibo yan ẹni to wa lati ilẹ Hausa, kí wọn si jina si awọn ẹya yooku. Àpẹẹrẹ dida ẹya si nìyẹn. "Tinubu lọ ipinlẹ Ogun, o sọ asiko Yoruba lokan ati oun lo kan. "Peter Obi lọ si ilẹ Igbo, o ni ki wọn ma dibo yan oun nitori oun jẹ igbo sugbọn nitori oun jẹ akikanju ọkùnrin ti isẹ ye. O ni ki ṣe asiko ẹnikẹni lati di aarẹ sugbọn o jẹ asiko fun awọn ọmọ orile-ede Naijiria lati yan adari wọn." | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cz5v440d30ro |
1entertainment
| Odunlade Adekola: Wo Aàmì èye tí Odunlade Adekola gbà ní AMVCA | Gbajugbaja oṣere tiata Nollywood to tun n gbe awo orin jade, Odunlade Adekọla ti gba ami ẹyẹ oṣere tiata ọkunrin to pegede julọ ni agbo oṣere. Odunlade bori awọn oṣere to kopa ninu fiimu Rattle Snake, Amina, Gold Coast Lounge ati awọn miran lati gba ami ẹyẹ naa. Ami ẹyẹ AMVCA ni wọn ma n fun awọn oṣere fiimu, awọn ti wọn jọ ṣe fiimu ati gbogbo awọn ti wọn jọ kopa ninu ẹ. Lara awọn akẹgbẹ rẹ to gboriyin fun Adekola ni Bukunmi Oluwashina to ṣe fiimu ''Jankariwo'' to fi gba ami ẹyẹ. Bukunmi lasiko to n gboriyin fun akẹgbẹ rẹ ni o jẹ moriya fun oun. Bakan naa lo dupẹ lọwọ oṣerekunrin naa ti oun pe si fiimu oun to si da loun nipa fiimu rẹ ''Jankariwo'''. ''A ṣe aṣeyọri lori fiimu Jankariwo. Iwuri nla lo jẹ fun mi bi wọn ṣe darukọ fiimu mi fun igba meji ni ami ẹyẹ to gajulọ ni ilẹ Afrika. ''Ẹ ku oriire ẹgbọn mi, ti mo n pe ni ''Number 1"', ẹ se ti ẹ jẹ iwurii ninu iṣẹ ti ẹ yan laayo.'' Bakan naa ni Bukunmi dupẹ pe o gbọ ipe oun lori fiimu naa, to si gboriyin fun pe iṣẹ nla to ṣe. ''Mo dupẹ lọwọ awọn to bami ṣiṣẹ naa ti wọn si jẹ ko ṣe aṣeyọri.'' Fiimu naa gba ami ẹyẹ gẹgẹ bi fiimu Yoruba akọkọ ti wọn yoo fi orukọ rẹ lede fun ami ẹyẹ ni ọna meji. Ami ẹyẹ Ilẹ Africa ti ''Africa Magic Viewers'Choice Awards (AMVCA), waye ni Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Karun un, 2022. Ami ẹyẹ naa ni awọn kan ma n pe ni ami ẹyẹ ti Oscar ti ilẹ Afrika, ti wọn ti n fun awọn oṣere fiimu, awọn to n gbe wọn jade ati awọn onimọ miran ni ẹka wọn. Ọdun yii ni ami ẹyẹ naa tun pada si ilẹ Afrika lẹyin ti wọn ko lee ṣe ni ọdun to kọja nitori ajakalẹ aarun Coronavirus. | Odunlade Adekola: Wo Aàmì èye tí Odunlade Adekola gbà ní AMVCA Gbajugbaja oṣere tiata Nollywood to tun n gbe awo orin jade, Odunlade Adekọla ti gba ami ẹyẹ oṣere tiata ọkunrin to pegede julọ ni agbo oṣere. Odunlade bori awọn oṣere to kopa ninu fiimu Rattle Snake, Amina, Gold Coast Lounge ati awọn miran lati gba ami ẹyẹ naa. Ami ẹyẹ AMVCA ni wọn ma n fun awọn oṣere fiimu, awọn ti wọn jọ ṣe fiimu ati gbogbo awọn ti wọn jọ kopa ninu ẹ. Lara awọn akẹgbẹ rẹ to gboriyin fun Adekola ni Bukunmi Oluwashina to ṣe fiimu ''Jankariwo'' to fi gba ami ẹyẹ. Bukunmi lasiko to n gboriyin fun akẹgbẹ rẹ ni o jẹ moriya fun oun. Bakan naa lo dupẹ lọwọ oṣerekunrin naa ti oun pe si fiimu oun to si da loun nipa fiimu rẹ ''Jankariwo'''. ''A ṣe aṣeyọri lori fiimu Jankariwo. Iwuri nla lo jẹ fun mi bi wọn ṣe darukọ fiimu mi fun igba meji ni ami ẹyẹ to gajulọ ni ilẹ Afrika. ''Ẹ ku oriire ẹgbọn mi, ti mo n pe ni ''Number 1"', ẹ se ti ẹ jẹ iwurii ninu iṣẹ ti ẹ yan laayo.'' Bakan naa ni Bukunmi dupẹ pe o gbọ ipe oun lori fiimu naa, to si gboriyin fun pe iṣẹ nla to ṣe. ''Mo dupẹ lọwọ awọn to bami ṣiṣẹ naa ti wọn si jẹ ko ṣe aṣeyọri.'' Fiimu naa gba ami ẹyẹ gẹgẹ bi fiimu Yoruba akọkọ ti wọn yoo fi orukọ rẹ lede fun ami ẹyẹ ni ọna meji. Ami ẹyẹ Ilẹ Africa ti ''Africa Magic Viewers'Choice Awards (AMVCA), waye ni Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Karun un, 2022. Ami ẹyẹ naa ni awọn kan ma n pe ni ami ẹyẹ ti Oscar ti ilẹ Afrika, ti wọn ti n fun awọn oṣere fiimu, awọn to n gbe wọn jade ati awọn onimọ miran ni ẹka wọn. Ọdun yii ni ami ẹyẹ naa tun pada si ilẹ Afrika lẹyin ti wọn ko lee ṣe ni ọdun to kọja nitori ajakalẹ aarun Coronavirus. | https://www.bbc.com/yoruba/media-61468257 |
5sports
| Joseph Yobo ni igbákejì akọ́nimọ̀ọ́gbá Super Eagles tuntun - NFF | Ajọ to n ri si ọrọ ere bọọlu ni Naijiria, NFF ti kede Joseph Yobo gẹgẹ bi igbakeji akọnimọgba ikọ naa tuntun. Yobo bọ si ipo yii lẹyin ti wọn fi ọwọ osi juwe ile fun Imama Amapakabo to di ipo na mu tẹlẹ. Ki Yobo to de ipo tuntun yii, o ti fi igba kan jẹ balogun ikọ Super Eagles to si ṣe aṣeyọri ninu idijẹ ifẹ ẹye ti ilẹ Afrika to waye lọdun 2013. Yobo ni ọpọ iriri gẹgẹ agbabọọlu latari bo ṣe ti gba bọọlu ni oriṣiriṣi ẹgbẹ agbabọọlu kaakiri agbaye. O gba igbega si ikọ Super Eagles lẹyin to ṣoju orilẹ-ede Naijiria ninu idije ọjẹ wẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ti ju ogun ọdun lọ lọdun 1999. Ko ti di pe Yobo fẹyinti gẹgẹ agbalọọlu fun ikọ Super Eagles, o ti kopa ninu idioje ife ẹyẹ agbaye nigba mẹta, ati ninu idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika nigba mẹfa. Lara awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti Yobo ti ṣeṣẹ tẹle ni ikọ Olympique Marseille, Everton, Norwich City ati Fenerbahçe. | Joseph Yobo ni igbákejì akọ́nimọ̀ọ́gbá Super Eagles tuntun - NFF Ajọ to n ri si ọrọ ere bọọlu ni Naijiria, NFF ti kede Joseph Yobo gẹgẹ bi igbakeji akọnimọgba ikọ naa tuntun. Yobo bọ si ipo yii lẹyin ti wọn fi ọwọ osi juwe ile fun Imama Amapakabo to di ipo na mu tẹlẹ. Ki Yobo to de ipo tuntun yii, o ti fi igba kan jẹ balogun ikọ Super Eagles to si ṣe aṣeyọri ninu idijẹ ifẹ ẹye ti ilẹ Afrika to waye lọdun 2013. Yobo ni ọpọ iriri gẹgẹ agbabọọlu latari bo ṣe ti gba bọọlu ni oriṣiriṣi ẹgbẹ agbabọọlu kaakiri agbaye. O gba igbega si ikọ Super Eagles lẹyin to ṣoju orilẹ-ede Naijiria ninu idije ọjẹ wẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ti ju ogun ọdun lọ lọdun 1999. Ko ti di pe Yobo fẹyinti gẹgẹ agbalọọlu fun ikọ Super Eagles, o ti kopa ninu idioje ife ẹyẹ agbaye nigba mẹta, ati ninu idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika nigba mẹfa. Lara awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti Yobo ti ṣeṣẹ tẹle ni ikọ Olympique Marseille, Everton, Norwich City ati Fenerbahçe. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51478929 |
1entertainment
| Orí kó Lateef Adedimeji yọ lọ́wọ́ ikú òjijì, ló bá mú orin ọpẹ́ sẹ́nu | Gbajumọ oṣere tiata, Lateef Adedimeji ti sọrọ sita pe diẹ lo ku ki oun ba ijamba ọkọ lọ lọjọ diẹ sẹyin ki ori to ko oun yọ.\nAdedimeji tu ọrọ yii sita lasiko to fi n fi orin ọpẹ sita lati fi imore han fun Ọlọrun loju opo Instagram rẹ. Adedimeji ṣalaye pe niọjọ diẹ sẹyin ni ijanu ọkọ oun kan ṣa dede ja lori ere ṣugbọn ti ori ko oun yọ lọwọ ijamba iku ojiji. “Iyin ni fun Ọlọrun alagbara. Melo ninu ore rẹ ni mo le ka tan? mo dupẹ fun ifẹ rẹ, mo dupẹ fun idile mi, mo dupẹ fun iyawo mi, O ṣeun ti o gba mi la, ti mo fi moribọ lọwọ iku lọjọ diẹ sẹyin nigba ti ijanu ọkọ mi kọṣẹ silẹ, ore ọfẹ rẹ ni...”\nIṣẹlẹ yii n waye pẹlu bi ayajọ ọdun kan ti Lateef Adedimeji gbe aya rẹ, Mo Bimpe niyawo ṣe ku si dẹdẹ. | Orí kó Lateef Adedimeji yọ lọ́wọ́ ikú òjijì, ló bá mú orin ọpẹ́ sẹ́nu Gbajumọ oṣere tiata, Lateef Adedimeji ti sọrọ sita pe diẹ lo ku ki oun ba ijamba ọkọ lọ lọjọ diẹ sẹyin ki ori to ko oun yọ.\nAdedimeji tu ọrọ yii sita lasiko to fi n fi orin ọpẹ sita lati fi imore han fun Ọlọrun loju opo Instagram rẹ. Adedimeji ṣalaye pe niọjọ diẹ sẹyin ni ijanu ọkọ oun kan ṣa dede ja lori ere ṣugbọn ti ori ko oun yọ lọwọ ijamba iku ojiji. “Iyin ni fun Ọlọrun alagbara. Melo ninu ore rẹ ni mo le ka tan? mo dupẹ fun ifẹ rẹ, mo dupẹ fun idile mi, mo dupẹ fun iyawo mi, O ṣeun ti o gba mi la, ti mo fi moribọ lọwọ iku lọjọ diẹ sẹyin nigba ti ijanu ọkọ mi kọṣẹ silẹ, ore ọfẹ rẹ ni...”\nIṣẹlẹ yii n waye pẹlu bi ayajọ ọdun kan ti Lateef Adedimeji gbe aya rẹ, Mo Bimpe niyawo ṣe ku si dẹdẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cnd5p5r4962o |
5sports
| Euro 2020: England fọ́ Croatia lẹ́nu ní Euro 2020, wo àwọn ohun tó ṣókùnkùn sí ọ nípa rìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà | Goolu kan lati ẹsẹ atamatase agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi, Raheem Sterling ni orilẹede England nilo lati fagba han Croatia ni ifẹsẹwọn wọn to waye loni nibi idije Euro 2020 to n lọ lọwọ. Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtadinlọgọta ni Kalving Phillips tẹ paasi si Sterling to si fi suuru gbee sile. Amọṣa Kalving Phillips lo gba oriyin gẹgẹ bi agbabọọlu to tan bi oorun ninu ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu oniruuru bira to da. Ninu ọrọ rẹ, akọnimọsgba orilẹede England, Gareth Southgate ni inu oun dun pupọ fun bi awọn agbabọọlu oun ṣe ṣe daradara si ninu ifẹsẹwọnsẹ naa. O ni lootọ yoo mu ẹru wiwo kuro lọrun awọn "ṣugbọn eyi ko tumọ si pe awọn ti pegede fun ipele to kan." Nibayii, orilẹede Scotland lawọn agbabọọlu England yoo maa koju bayii. Lọjọ Ẹti ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye ni papa iṣire Wembley. Croatia ni tiwọn yoo maa koju Czeck Republic. | Euro 2020: England fọ́ Croatia lẹ́nu ní Euro 2020, wo àwọn ohun tó ṣókùnkùn sí ọ nípa rìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà Goolu kan lati ẹsẹ atamatase agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi, Raheem Sterling ni orilẹede England nilo lati fagba han Croatia ni ifẹsẹwọn wọn to waye loni nibi idije Euro 2020 to n lọ lọwọ. Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtadinlọgọta ni Kalving Phillips tẹ paasi si Sterling to si fi suuru gbee sile. Amọṣa Kalving Phillips lo gba oriyin gẹgẹ bi agbabọọlu to tan bi oorun ninu ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu oniruuru bira to da. Ninu ọrọ rẹ, akọnimọsgba orilẹede England, Gareth Southgate ni inu oun dun pupọ fun bi awọn agbabọọlu oun ṣe ṣe daradara si ninu ifẹsẹwọnsẹ naa. O ni lootọ yoo mu ẹru wiwo kuro lọrun awọn "ṣugbọn eyi ko tumọ si pe awọn ti pegede fun ipele to kan." Nibayii, orilẹede Scotland lawọn agbabọọlu England yoo maa koju bayii. Lọjọ Ẹti ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye ni papa iṣire Wembley. Croatia ni tiwọn yoo maa koju Czeck Republic. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57461783 |
2health
| Nigeria lockdown: Kí ni àwọn kókó tí Ààrẹ Buhari tẹnumọ́ nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ lọ́jọ́ Àìkú? | Lootọ ni Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti kede pe ko ni si lilọ bibọ ọkọ ati eniyan nipinlẹ Eko, Ogun ati ilu Abuja, ṣugbọn ofin yii ko de awọn kan. Eyi ko ṣẹyin bi iṣẹ wọn ṣe ṣe pataki si igbaye-gbadun awọn araalu. Lara awọn eniyan naa lati ri awọn to n ṣiṣẹ ni awọn ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ, awọn ileeṣẹ iroyin radio ati amohunmaworan, awọn oniweeroyin, to si le fi ẹri han pe awọn ko le ṣiṣẹ lati ile wọn. Bakan naa ni ko yọ awọn ileeṣẹ to n ṣe nkan ti ẹnu njẹ, awọn ileepo bẹtiro, awọn ileeṣẹ eleto aabo ti ijọba ati aladani to fi mọ ileeṣẹ amunawa. Eyi ko yọ awọn oṣiṣẹ ileewosan, awọn ile itaja ogun silẹ. Ẹwẹ, iaarẹ sọ pe awọn ọkọ ti yoo lanfaani lati rin loju popo ni awọn ọkọ to ba ko ounjẹ ati ohun eelo itọju alaisan. Aarẹ Muhammadu Buhari ti kede awọn igbesẹ tuntun lori ọna ati wawọ ajakalẹ arun Coronavirus lorilẹede Naijiria. Aarẹ Buhari ni awọn igbesẹ naa da lori amọran ileeṣẹ eto ilera nijọba apapọ ati ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria Aarẹ ni lootọ inira pupọ ni igbesẹ yii yoo mu ba awọn ọmọ orilẹede Naijiria ṣugbọn ọrọ arun coronavirus lorilẹede Naijiria bayii ti di tiku-tiye; o ti di ọrọ sunnukun to nilo amojuto pẹlu oju sunnukun. Aarẹ ni pẹlu bi nnkan ṣe yọri si fun awọn eeyan orilẹede bii Italy ati Faranse, ko si ifarada to pọju fun ati koju aru naa ko to gba aorilẹede Naijiria kan. | Nigeria lockdown: Kí ni àwọn kókó tí Ààrẹ Buhari tẹnumọ́ nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ lọ́jọ́ Àìkú? Lootọ ni Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti kede pe ko ni si lilọ bibọ ọkọ ati eniyan nipinlẹ Eko, Ogun ati ilu Abuja, ṣugbọn ofin yii ko de awọn kan. Eyi ko ṣẹyin bi iṣẹ wọn ṣe ṣe pataki si igbaye-gbadun awọn araalu. Lara awọn eniyan naa lati ri awọn to n ṣiṣẹ ni awọn ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ, awọn ileeṣẹ iroyin radio ati amohunmaworan, awọn oniweeroyin, to si le fi ẹri han pe awọn ko le ṣiṣẹ lati ile wọn. Bakan naa ni ko yọ awọn ileeṣẹ to n ṣe nkan ti ẹnu njẹ, awọn ileepo bẹtiro, awọn ileeṣẹ eleto aabo ti ijọba ati aladani to fi mọ ileeṣẹ amunawa. Eyi ko yọ awọn oṣiṣẹ ileewosan, awọn ile itaja ogun silẹ. Ẹwẹ, iaarẹ sọ pe awọn ọkọ ti yoo lanfaani lati rin loju popo ni awọn ọkọ to ba ko ounjẹ ati ohun eelo itọju alaisan. Aarẹ Muhammadu Buhari ti kede awọn igbesẹ tuntun lori ọna ati wawọ ajakalẹ arun Coronavirus lorilẹede Naijiria. Aarẹ Buhari ni awọn igbesẹ naa da lori amọran ileeṣẹ eto ilera nijọba apapọ ati ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria Aarẹ ni lootọ inira pupọ ni igbesẹ yii yoo mu ba awọn ọmọ orilẹede Naijiria ṣugbọn ọrọ arun coronavirus lorilẹede Naijiria bayii ti di tiku-tiye; o ti di ọrọ sunnukun to nilo amojuto pẹlu oju sunnukun. Aarẹ ni pẹlu bi nnkan ṣe yọri si fun awọn eeyan orilẹede bii Italy ati Faranse, ko si ifarada to pọju fun ati koju aru naa ko to gba aorilẹede Naijiria kan. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-52088417 |
4religion
| Catholic Seminary Attack: Ọkadà ní agbébọn gùn wọ iléẹ̀kọ́ Àgùdà láti jí èèyàn gbé | O kere tan awọn agbebọn ti ji awọn akẹkọọ mẹta gbe lọ ni ileẹkọ imọ ijọ ''Catholic'' ni ipinlẹ Kaduna. Ileeṣẹ ọlọpaa to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ni awọn agbebọn naa wa ni ọgọọrọ wọn si ileẹkọ ''Catholic Seminary'' ti wọn si ji awọn akẹkọọ gbe, ti awọn miran si farapa. Ọlọpaa naa ni awọn agbebọn naa lo ọkada lati fi wọ ileẹkọ ''Saint Albert Seminary'' ni agbegbe Kagoma, ti wọn si ṣina bolẹ, ti wọn si salọ. Ileeṣẹ ọlọpaa naa ni awọn ti wọn farapa naa ti wa ni ileewosan, ti wọn si ti bẹrẹ si ni wa awọn agbebọn naa. Lara awọn akẹkọọ ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni awọn ko le e sọ ni pato iye akẹkọọ ti awọn agbebon jigbe lọ. Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni ibọn alagbara ni awọn agbebọn da bolẹ lasiko ti awọn akẹkọọ naa ṣẹṣẹ pari adura irọlẹ tan ni ṣọọṣi to wa ni ileẹkọ naa. Wẹrẹ ti awọn akẹkọọ bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn bayii ni wọn fi ẹsẹ fẹ, ti olukaluku si bẹrẹ si ni sa asala fun ẹmi wọn. ''Awọn ti ori ko yọ nikan ni wọn jajabọ lọwọ awọn ajinigbe naa, ti wọn si ko awọn akẹkọọ ti a ko tii le sọ iye wọn. '' Wọn kesi ijọba lati wa wọrọkọ fi ṣe ada lori ijinigbe ojoojumọ ni awọn ileẹkọ to wa ni ariwa orilẹede Naijiria, ki wọn le doola ẹmi awọn eniyan. O kere tan akẹkọọ to le ni ẹgbẹrun ni awọn ajinigbe ti jigbe lọ ni ileẹkọ girama ati fasiti, bẹrẹ lati Oṣu Kejila, ọdun to kọja. Ọpọlọpọ awọn agbebọn yii ni wọn n bere fun owo ẹmi awọn ti wọn ba jigbe, ki wọn to doola ẹmi wọn. Ileeṣẹ ọmọogun orilẹede Naijiria ni awọn ti ran ikọ ọmọogun ni ẹgbẹgbẹrun wọn lọ si awọn agbegbe yii. Bakan naa ni wọn pa awọn ẹrọ ayelujara ati ẹrọ ibanisọrọ ni awọn agbegbe wonyii, ki ọwọ le tete tẹ awọn ajinigbe to n da ẹmi awọn eniyan legbodo ni ojoojumọ. Amo gbogbo igbiyanju yii pabo lo jasi, nitori awọn agbebọn yii ṣi n ṣọṣẹ ni gbogbo igba, ti wọn si n fi ẹmi awọn akẹkọọ ati olukọ ṣofo, to fi mọ awọn araalu. Wọn ti gba awọn obinrin ni imọran pe ki wọn o má fún awọn ọkunrin ni ibalopọ, ti wọn ba fi kọ lati gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19. Eyi ko sẹyin bi ọpọ eeyan ko fẹ ẹ gba abẹrẹ naa kaakiri agbaye. Ni orilẹ-ede South Africa, imọran ti wọn gba awọn obinrin naa di dandan paapaa bi awọn ọkunrin ni Eastern Cape ṣe kọ ẹyin si abẹrẹ naa. Gẹgẹ bi iroyin ti Daily Maverick gbe jade l'oṣu Kẹsàn-án, oludari ajọ to n mojuto eto ilera ni agbegbe naa, Nomakhosazana Meth lo fi ikede naa sita. O ni imọran naa wulo, paapaa fun awọn obinrin ti ko ti i ṣe igbeyawo. Eyi yoo si daabo bo "ẹyin mejeeji". Obìnrin lo pọ ju ninu awọn to ti gba abẹrẹ. Eeyan to le ni miliọnu kan lo si ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni agbegbe Eastern Cape, bo tilẹ jẹ pe miliọnu mẹrin aabọ ni afojusun awọn alasẹ, ti yoo ba fi di oṣu Kẹrin, ọdun to n bọ. | Catholic Seminary Attack: Ọkadà ní agbébọn gùn wọ iléẹ̀kọ́ Àgùdà láti jí èèyàn gbé O kere tan awọn agbebọn ti ji awọn akẹkọọ mẹta gbe lọ ni ileẹkọ imọ ijọ ''Catholic'' ni ipinlẹ Kaduna. Ileeṣẹ ọlọpaa to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ni awọn agbebọn naa wa ni ọgọọrọ wọn si ileẹkọ ''Catholic Seminary'' ti wọn si ji awọn akẹkọọ gbe, ti awọn miran si farapa. Ọlọpaa naa ni awọn agbebọn naa lo ọkada lati fi wọ ileẹkọ ''Saint Albert Seminary'' ni agbegbe Kagoma, ti wọn si ṣina bolẹ, ti wọn si salọ. Ileeṣẹ ọlọpaa naa ni awọn ti wọn farapa naa ti wa ni ileewosan, ti wọn si ti bẹrẹ si ni wa awọn agbebọn naa. Lara awọn akẹkọọ ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni awọn ko le e sọ ni pato iye akẹkọọ ti awọn agbebon jigbe lọ. Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni ibọn alagbara ni awọn agbebọn da bolẹ lasiko ti awọn akẹkọọ naa ṣẹṣẹ pari adura irọlẹ tan ni ṣọọṣi to wa ni ileẹkọ naa. Wẹrẹ ti awọn akẹkọọ bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn bayii ni wọn fi ẹsẹ fẹ, ti olukaluku si bẹrẹ si ni sa asala fun ẹmi wọn. ''Awọn ti ori ko yọ nikan ni wọn jajabọ lọwọ awọn ajinigbe naa, ti wọn si ko awọn akẹkọọ ti a ko tii le sọ iye wọn. '' Wọn kesi ijọba lati wa wọrọkọ fi ṣe ada lori ijinigbe ojoojumọ ni awọn ileẹkọ to wa ni ariwa orilẹede Naijiria, ki wọn le doola ẹmi awọn eniyan. O kere tan akẹkọọ to le ni ẹgbẹrun ni awọn ajinigbe ti jigbe lọ ni ileẹkọ girama ati fasiti, bẹrẹ lati Oṣu Kejila, ọdun to kọja. Ọpọlọpọ awọn agbebọn yii ni wọn n bere fun owo ẹmi awọn ti wọn ba jigbe, ki wọn to doola ẹmi wọn. Ileeṣẹ ọmọogun orilẹede Naijiria ni awọn ti ran ikọ ọmọogun ni ẹgbẹgbẹrun wọn lọ si awọn agbegbe yii. Bakan naa ni wọn pa awọn ẹrọ ayelujara ati ẹrọ ibanisọrọ ni awọn agbegbe wonyii, ki ọwọ le tete tẹ awọn ajinigbe to n da ẹmi awọn eniyan legbodo ni ojoojumọ. Amo gbogbo igbiyanju yii pabo lo jasi, nitori awọn agbebọn yii ṣi n ṣọṣẹ ni gbogbo igba, ti wọn si n fi ẹmi awọn akẹkọọ ati olukọ ṣofo, to fi mọ awọn araalu. Wọn ti gba awọn obinrin ni imọran pe ki wọn o má fún awọn ọkunrin ni ibalopọ, ti wọn ba fi kọ lati gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19. Eyi ko sẹyin bi ọpọ eeyan ko fẹ ẹ gba abẹrẹ naa kaakiri agbaye. Ni orilẹ-ede South Africa, imọran ti wọn gba awọn obinrin naa di dandan paapaa bi awọn ọkunrin ni Eastern Cape ṣe kọ ẹyin si abẹrẹ naa. Gẹgẹ bi iroyin ti Daily Maverick gbe jade l'oṣu Kẹsàn-án, oludari ajọ to n mojuto eto ilera ni agbegbe naa, Nomakhosazana Meth lo fi ikede naa sita. O ni imọran naa wulo, paapaa fun awọn obinrin ti ko ti i ṣe igbeyawo. Eyi yoo si daabo bo "ẹyin mejeeji". Obìnrin lo pọ ju ninu awọn to ti gba abẹrẹ. Eeyan to le ni miliọnu kan lo si ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni agbegbe Eastern Cape, bo tilẹ jẹ pe miliọnu mẹrin aabọ ni afojusun awọn alasẹ, ti yoo ba fi di oṣu Kẹrin, ọdun to n bọ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58856375 |
2health
| Corornavirus: Kini Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti ṣe fun baba tọ ni ọmọ òun ko gbọdọ tèlé oun déle nitori o ṣẹ̀ṣẹ̀ de lati Eko? | Gómìnà ìpínlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ni òun ti yan baba ti fọran rẹ tan ka ori ayelujara lásìkò to n ba ọmọ rẹ jà pe ko le tẹ̀lé òun lọ ile lai ṣe ayẹwò Covid-19 lẹ́yìn to ti irin ajo de lati ìpínẹ̀ Eko gẹ́gẹ́ bi asoj;u ìjọba lori ọ̀rọ̀ Covid-19 nipinlẹ Ekiti. Gomina fi ọ̀rọ́ yìí léde lorí atẹjísẹ́ twitter rẹ̀ lasàn òní pe inú oun dùn fún igbésẹ ọ̀gbẹ́ni Femi Adeoye pẹlu bi o ṣe ṣe pẹlu ọmọ bíbí rẹ̀ nítori pé o ni igboya, o si nifẹ ìpińll Ekiti lọ́kan. O ní ọ̀gbẹ́ ni Adeoye yoo ran ìjọba lọ́wọ́ láti maa tan àwọn ipolongo lori ààrun corornavirus, yóò si jẹ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe lori ọ̀rọ̀ coronavirus nípìnlẹ̀ Ekiti O kò leè wọ inú ilé mi lẹ́yìn ìrìnàjò láti Eko, lai ṣe àyẹ̀wò Coronavirus - Bàbá yari fún ọmọ Coronavirus symptoms vs cold-O kò leè wọ inú ilé mi lẹ́yìn ìrìnàjò láti Eko, lai ṣe àyẹ̀wò Coronavirus - Bàbá yari fún ọmọ Yorùbá ni ọmọ ẹni kii burú títí, ká lè fún ẹkùn pa jẹ àmọ́ èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹlu bàbá kan ni Ondo, tó le ọmọ rẹ síta nítorí ibẹru àrùn Coronavirus. Bí ere orí itage si ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ri nigbati bàbá kan, Arákùnrin Babafemi, yari kanlẹ pé ọmọ òun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ìlú Èkó de, gbọ́dọ̀ ṣe ayẹwo àrùn Coronavirus, kí òun tó gbà á sínú ilé . Babafemi, tíì ṣe òṣìṣẹ́ fẹyinti kan nileesẹ àjọ ẹsọ ojú pópó FRSC ṣàlàyé pé, òun ti sọ fún ọmọ òun láti dúró sí Eko, àmọ́ tí kò gbọ . "Mo ti ní kí ọmọ mi má ṣe wá sí Ado Ekiti àmọ́ kò gbọ ọrọ si mi lẹ́nu. Ní báyìí tó sì ti dé sí Ado, ó gbọ́dọ̀ ṣe ayẹwo àrùn Coronavirus ni, kò to dára pọ mọ wa." Babafemi ni kí òun to gba ọmọ òun sínú ilé, yóò kọ́kọ́ lo ọjọ́ mẹ́rìnlá na ni ibùdó iyasọtọ nítorí òun kò leè fi ẹbí òun sínú ewu àrùn Covid-19. Baba náà ni ó yẹ kí òun fi ọ̀rọ̀ obìnrin oloyun tó wà sì Èkìtì láti ìlú Èkó ṣe arikọgbọn, ẹni tó ko àrùn Coronavirus wá Ekiti láti Eko. Awọn to ji Komisana eto ọgbin gbe ni ipinlẹ Ekiti ọgbẹni Folorunsho Olabode gbe ti beere ọgbọn miliọnu naira gẹgẹ bi owo tawọn yoo gba ki wọn to tu silẹ. Ni irọlẹ ọjọ Aiku lawọn ajinigbe yi da ọkọ rẹ lọna ni opopona Isan Iludun ni Ekiti. Wọn ji Kọmisana naa ati eeyan kan ti wọn jọ wa ninu ọkọ gbe ti wọn si tun yinbọn pa Kansilọ nijọba ibilẹ Ilejemeje kan ti wọn jọ wa ninu ọkọ naa. Ninu ohun ta ri gbọ ninu awọn iwe iroyin ilẹ Naijiria,eeyan kan ninu mọlẹbi Kọmisana sọ fun awọn akọroyin ni iAdo Ekiti lọjọ Aje pe awọn ajinigbe naa ti pe awọn lori ago ti wọn si ti beere owo ẹmi ọgbọn miliọnu naira. Eni ta n wi yi sọ pe ninu ibẹrubojo ni awọn eeyan ilu Kọmisana naa ti se Iye wa ti wọn si n rawọ ẹbẹ si Gomina la ti sa gbogbo agbara lati ri pe wọn doola ẹmi ọmọ awọn. ''A n bẹ Gomina Kayode Fayemi ati awọn agbofinro lati sa gbogbo agbara wọ́n ki wọn ba le doola rẹ'' Ewẹ alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekoto Sunday Abutu to tẹpẹlẹmọ ipinu ajọ naa lati wa Kọmisana naa jade ni awọn ko mọ si owo ẹmi tawọn ajinigbe naa n beere. ''A ko mọ si pe awọn ajinigbe naa n beere owo ki wọn to tusilẹ.Wọn o ti sọ fun wa'' Bakanna ni ọkan lara awọn ọmọ ile asofin nipinlẹ Ekiti ti ni ara ohun ti Coronavirus da silẹ ni ijingbe yi jẹ nitori ohun ni ko jẹ ki wọn se ifilọlẹ ikọ alaabo Amọtẹkun lasiko. Tope Ogunleye to n soju ẹkun idibo Ilejemeje ni ''inu mi ko dun si gbogbo ohun to n sẹlẹ yi.Awọn ọdaran yi ko sẹsẹ ma sọsẹ laaye ibi ti wọn ti ji Kọmisana gbe.Mo mọ wi pe Gomina Fayemi ko fi ọrọ yi sere rara'' Ogunleye ni nigba ti Covid-19 yoo ba fi kasẹ nilẹ, gomina yoo raaye lati se ifilọlẹ ikọ Amọtẹkun. O sọ pe awọn eeyan awọn to mọ tibu toro agbegbe naa ni yoo wa nibẹ ti wọn yoo si le awọn ọdaran kuro ni ipinlẹ Ekiti. Ina nla kan tun sọ lọsan oni lagbegbe college Road Road, Abatan Ọgba ni ilu Eko. Titi di asiko ti a fi n ṣa iroyin yii jọ, ko tii si ẹni lee sọ ohun gan ni pato to fa ijamba ina naa. Ileepo NNPC to wa ni agbegbe naa ni ina naa ti sọ eyi ti o jo ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye. Gbajumọ akọroyin àti olóṣèlú kan, Dele Momoodu tí woye pe o ṣeé ṣe kí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà wo, tí àwọn aráàlú bá fi bínú lórí àfikún igbele àrùn Coronavirus. Dele Momoodu, lásìkò to ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé, kí ìjọba tí àwọn èèyàn mọle kọ ní ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tó wà láti dènà àrùn Coronavirus. "Tí ẹ bá wo orílẹ̀ èdè Ghana, ó ní ọ̀nà tí ìjọba ń gba láti dènà ifarakinra. Yorùbá si ní ebi kii wọnú, kí ọ̀rọ̀ miran wọ, ebi sì ni ìṣòro ni orílẹ̀ èdè wa". "Ilẹ̀ Nàìjíríà kii se UK, Amẹ́ríkà àti Faranse. Kò sí oúnjẹ, kò sì iná, ẹ wá fẹ tí àwọn èèyàn mọle, kò leè ṣeé ṣe, èmi kò sì mọ bí ijọba wá ṣe fẹ ṣe. " Bákan náà ni Dele Momoodu koro ojú sì bí ìjọba ṣe kó owó sórí tabili, tí wọn sì ń pín bíi ìgbà tí wọn ń pín àkàrà, èmi kò sì tíì rí èèyàn tó ní òun ti rí owó náà gbà. "A ti pariwo títí fún ìjọba, wọn kò gbọ, Nàìjíríà kò sì ní àkọsílẹ̀ gidi. Kí ló dé tí ìjọba kò ṣe lọ nọ́mbà àsùnwọ̀n owó ni banki láti fi pín owó náà àti pé ọna wo ni wọn gba mọ àwọn aláìní." Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí akojọpọ esi tí ileesẹ tó ń gbógun ti àrùn nilẹ yìí, Momoodu ni Naijiria kò ní àkọsílẹ̀ tó dára lórí iye èèyàn tó ní Coronavirus ni Naijiria, bẹ́ẹ̀ sì ni ọpọ àwọn èèyàn tó wà nibẹ lo ń fẹ́ jẹun láti ara àìsàn náà. Lórí erongba aṣáájú ẹgbẹ́ APC àti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Eko tẹ́lẹ̀, Senato Bola Hammed Tinubu láti di aarẹ Naijiria lọ́dún 2023, Momoodu ni lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, Tinubu sì lo kajuẹ julọ láti darí orílẹ̀ èdè yìí. O ṣàlàyé pé lóòótọ́ ni Tinubu kò fẹ́ lórí bí àwọn èèyàn ṣe ń pariwo rẹ pé kò wá díje nítorí ó ti ìgbésẹ ọhun bíi ìwà ọyaju sì aarẹ Buhari to wa lori aleefa, nígbà tí kò tíì parí ṣáá isejọba rẹ. Momoodu ni "Ọpọlọpọ owó tí awọn eniyan kan ní Tinubu kò yìí, kii na fún ara rẹ nìkan nítorí pé ó ní ojú àánú pupọ, tó sì máa ń rán aráàlú lọ́wọ́,koda tipátipá lọ máa ń fi jẹun." "Bí APC ba fà Olóye Tinubu silẹ láti díje fún ipò Ààrẹ Naijiria, ó dá mi lójú pé, ó tó gbangba sùn lọyẹ, òun ni yóò mókè laarin awọn oludije yòókù nítorí pé ó kúnjú òṣùwọ̀n, tí yóò sì soro kò tó má di aarẹ Nàìjíríà." Momoodu tún woye pe ìlànà wiwo ọ̀rọ̀ ẹṣin, ẹ̀yà àti owó láti fà oludije kalẹ ni Naijiria kò bójú mú nítorí ẹni tí kò bá ní owó láti pin tàbí jẹ́ ẹlẹ́ṣin tó kàn láti díje, wọn kò ní ṣe atileyin gùn onitohun. Titi di ọjọ Kejila, oṣu Kinni, ọdun 2020, orilẹ-ede China nikan lo tii ni awọn to ni aarun coronavirus. Sugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ kẹtala, oṣu Kínní, aarun naa ti di ti gbogbo agbaye, nitori pe orilẹ-ede bi Thailand, Japan, South Korea àti America ṣe bẹ̀rẹ̀ si i ni akọsilẹ ti wọn naa. Lẹyin naa ni aarun naa bẹ̀rẹ̀ si tàn de awọn orilẹ-ede yooku, to fi mọ Africa. Lọwọ-lọwọ, o ti to miliọnu meji eniyan to ti ni aarun naa. Itan Iṣẹlẹ COVID 19 ní Naijiria: Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ni Naijiria kọkọ ni akọsilẹ aarun naa, lẹyin ti ọmọ orilẹ-ede Italy kan ni i.Lẹyin naa ni akọsilẹ ẹni keji waye lọjọ kẹsàn-án, oṣu Kẹta. Ọmọ Naijiria ni.Lẹyin eyi ni awọn to ni n pọ si. Níbo ni ọrọ coronavirus de duro bayii ni Naijiria? Lọwọ lọwọ, eniyan irinwo ati meje ni ajọ to n dena aarun ni Naijiria, NCDC, sọ pe o ni coronavirus. Awọn ipinlẹ ti aarun naa ti de ni Lagos Abuja Osun Edo Oyo Bauchi Akwa Ibom Kaduna Ogun Enugu Ekiti Kwara Rivers Benue Ondo Delta Katsina Anambra Niger Kano Apapọ wọn jẹ: mọkandinlogun ati Abuja to jẹ olu ilu Naijiria. Àwọn ipinlẹ ti Covid-19 ko ti i de ni NaijiriaBi aarun yii ṣe n tankalẹ to naa ni a ṣi ni awọn ipinlẹ ti ko tii de ni Naijiria. Ipinlẹ mẹrindinlogun ni coronavirus ko ti i de ni Naijiria naa niwọnyii:.Gombe Adamawa Plateau Borno Ebonyi Cross River Sokoto Kebbi Imo Bayelsa Taraba Kogi Nasarawa Zamfara Yobe Jigawa Igbesẹ wo ni wọn n gbe lati ri pe ajakalẹ aarun yii ko de ipinlẹ wọn? Lootọ ni coronavirus ko ti i de awọn ipinlẹ naa, sugbọn lati igba to ti de Naijiria ni diẹ lara wọn ti gbe awọn igbesẹ lati ri i daju pe ko wọ ipinlẹ wọn, àti ọna ti wọn yoo gba koju rẹ to ba ṣèèṣì wọle. Ipinlẹ Borno gbé igbimọ amusẹya kalẹ lati sisẹ pẹlu awọn ileesẹ aladani, ile ijọsin ati awọn ajọ ti kii se ti jọba lati koju aarun naa, to ba fi le wọ ibẹ. Lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ipinlẹ Kebbi kede pe ki gbogbo ileewe o wa ni titi pa.Ipinlẹ Ebonyi naa fi ofin de ipejọpọ ọpọ eniyan, lọjọ kẹtalelogun, ọsu kẹta. Bakan naa ni ipinlẹ Bayelsa ati Imo kede lọjọ kẹrindinlọgbọn pe ki awọn ileewe di titi pa, wọn si tun fi ofin de ipejọpọ ọpọ eniyan to ba le ni àádọ́ta. Ni ti ipinlẹ Abia, o ti gbogbo ẹnu ibode ipinlẹ naa pa fun ọsẹ mẹrin, o si tun pasẹ pe ki gbogbo araalu o joko sile. Àwọn ile itaja oúnjẹ àti òògùn nìkan ni ofin naa yọ silẹ. Ijọba ipinlẹ Cross River fi ofin de ipejọpọ nile ijọsin.Kebbi àti Taraba ko ti ẹ gba ki ẹnikẹni wọle si tabi jade kuro ni ipinlẹ naa. Niṣe lo yẹ ki onikaluku maa fọwọ wọn loorekoore ki wọn si tẹle gbogbo imọran ajọ WHO lori didẹkun itankalẹ ajakalẹ aarun coronavirus laisko yii. ''O lè kó coronavirus nípa ṣíṣe eré ìdárayá, ẹ gbélé yín lásìkò yìí,''- onímọ̀ ètò ìlera Coronavirus in Nigeria: ''Èèyàn lè kó coronavirus nípa ṣíṣe eré ìdárayá, ẹ gbélé yín lásìkò yìí,'' Onimọ nipa eto ilera, Dokita Ikubese Wilson ṣe atupalẹ bi eeya ti le ko aarun coronavirus nipasẹ ṣiṣe ere idaraya. Ilana ijinasiraẹni jẹ ọkan gboogi lara awọn igbesẹ ti ajọ eto ilera agbaye, WHO gbe kalẹ gẹgẹ bi ara ọna ti a le gba dena itankalẹ aarun Coronavirus. Àwọn Ìpínlẹ̀ tí coronavirus kò tíì dé ní Nàìjíríà, àti ìgbésẹ̀ tí wọ́n ń gbé láti dènà rẹ̀ Nitorinaa, ko jẹ iyalẹnu pe ilana ijinasiraẹni yii wa lara awọn igbesẹ ti ijọba lẹkajẹka gbogbo ni orilẹede Naijiria tẹnpẹlẹ mọ julọ gẹgẹ bi ọna lati din ọwọja aarun naa ku nilẹ yii. Lati fi idi ilana naa mulẹ, awọn ijọba ipinlẹ bii Eko tilẹ fi ofin gbee lẹyin, ofin yii si wa lara eyi ti wọn gbe kalẹ ni ile ẹjọ lati fi gbajugbaja oṣere sinima, Funkẹ Akindele ati ọkọ rẹ j'ofin ni ọjọ Aje. Amọṣa, ohun to wa n ṣe ọpọ ni haahinin bayii ni bi awọn eeyan ko ṣe karamasiki ilana yii. Bi o tilẹ jẹ wi pe ijọba apapọ paṣẹ konile-o-gbele lawọn ipinlẹ kan bii Eko, Ogun ati Abuja, ohun ti o n farahan bayii paapaa lori ayelujara ni pe ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn ko fẹ ki jijoko pa sile o sọ awọn di nnkan miran ti wọn si ti bẹrẹ ere idaraya kaakiri lati fi na eegun ati ara wọn. Amọṣa o, nipasẹ ṣiṣe eyi, ọpọ wọn lo ti n darapọ mọ ibi ti ọpọ ero wa, ti wọn si ti n t'ipasẹ bẹẹ fi ara wọn sinu ewu ati ko arun Coronavirus. Nibayii ọpọ aworan eyi lo si ti lu ori ayelujara pa. Ọpọ igba ni igbesẹ ijọba lo ti ba oniruru iha araalu pade. Arabinrin kan to ni ki a fi orukọ bo oun laṣiri ṣalaye pe ni agbegbe ti oun n gbe ni ilu Eko ni oun ti maa n ṣe ere idaraya lati na eegun ati ara oun. O ni nigba ti oun yoo fi jade ni ọjọ Aje, 'igboro ti daru' loun lee fi we nitori iye awọn to wa nigboro lati ṣe ere idaraya. O ni eyi lo mu ki oun pinnu lati dawọ duro naa. Ni aipẹ yii ni awọn olujọsin ni mọṣalaṣi kan ni ilu Eko kọlu awọn oṣiṣẹ ikọ amuṣẹya ti ijọba gbe kalẹ ti wọn wa kan si wọn pe ki wọn pa ofin naa mọ nitori nṣe ni ileejọsin naa kun bamubamu fun awọn to wa kirun. Njẹ eeyan le ko aarun coronavirus nipa ṣiṣe ere idaraya? Onimọ nipa eto ilera, Dokita Ikubese Wilson ṣe atupalẹ bi eeya ti le ko aarun coronavirus nipasẹ ṣiṣe ere idaraya. Dokita Wilson ṣalaye pe o ṣeeṣe ki eeyan ti ipasẹ ere idaraya ko aarun covid-19 nitori sisun mọ ẹni to ni aarun naa lara. Bakan naa lo sọ pe kokoro aarun covid-19 le wa laaye yala lara ohun elo ere idaraya ti ẹni to ni aarun naa ba ti lo, nitorinaa ''asiko yii ko dara fun ṣiṣe ere idaraya nitori ewu to wa nibẹ pọ.'' Dokita Wilson tun ṣalaye pe ti eeyan ba n ṣe ere idaraya, eemi ẹni naa maa pọ si, bakan naa ni afẹfẹ to n jade lati inu ẹdọ foro naa yoo pọ si. ''Ti ẹni to n ṣe ere idaraya ba mi, eemi naa yoo maa jade leralera, ti ẹni naa ba si ni aarun coronavirus, ẹlomiiran ti wọn jọ n ṣe ere iadaraya le ko aarun naa lara rẹ,'' Dokita Wilson lo woye bẹẹ. O rọ awọn eeyan lati maa ṣe ere idaraya ninu ile wọn lasiko ti ofin konle-o-gbele wa lode nitori ewu to wa ninu ṣiṣe ere idaraya loju popo tabi ni gbọngan ere idaraya lasiko yii. O ni fifi ẹmi ẹlomiiran wewu ni ṣiṣe ere idaraya pẹlu awọn mii tumọ sii lasiko yii. | Corornavirus: Kini Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti ṣe fun baba tọ ni ọmọ òun ko gbọdọ tèlé oun déle nitori o ṣẹ̀ṣẹ̀ de lati Eko? Gómìnà ìpínlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ni òun ti yan baba ti fọran rẹ tan ka ori ayelujara lásìkò to n ba ọmọ rẹ jà pe ko le tẹ̀lé òun lọ ile lai ṣe ayẹwò Covid-19 lẹ́yìn to ti irin ajo de lati ìpínẹ̀ Eko gẹ́gẹ́ bi asoj;u ìjọba lori ọ̀rọ̀ Covid-19 nipinlẹ Ekiti. Gomina fi ọ̀rọ́ yìí léde lorí atẹjísẹ́ twitter rẹ̀ lasàn òní pe inú oun dùn fún igbésẹ ọ̀gbẹ́ni Femi Adeoye pẹlu bi o ṣe ṣe pẹlu ọmọ bíbí rẹ̀ nítori pé o ni igboya, o si nifẹ ìpińll Ekiti lọ́kan. O ní ọ̀gbẹ́ ni Adeoye yoo ran ìjọba lọ́wọ́ láti maa tan àwọn ipolongo lori ààrun corornavirus, yóò si jẹ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe lori ọ̀rọ̀ coronavirus nípìnlẹ̀ Ekiti O kò leè wọ inú ilé mi lẹ́yìn ìrìnàjò láti Eko, lai ṣe àyẹ̀wò Coronavirus - Bàbá yari fún ọmọ Coronavirus symptoms vs cold-O kò leè wọ inú ilé mi lẹ́yìn ìrìnàjò láti Eko, lai ṣe àyẹ̀wò Coronavirus - Bàbá yari fún ọmọ Yorùbá ni ọmọ ẹni kii burú títí, ká lè fún ẹkùn pa jẹ àmọ́ èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹlu bàbá kan ni Ondo, tó le ọmọ rẹ síta nítorí ibẹru àrùn Coronavirus. Bí ere orí itage si ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ri nigbati bàbá kan, Arákùnrin Babafemi, yari kanlẹ pé ọmọ òun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ìlú Èkó de, gbọ́dọ̀ ṣe ayẹwo àrùn Coronavirus, kí òun tó gbà á sínú ilé . Babafemi, tíì ṣe òṣìṣẹ́ fẹyinti kan nileesẹ àjọ ẹsọ ojú pópó FRSC ṣàlàyé pé, òun ti sọ fún ọmọ òun láti dúró sí Eko, àmọ́ tí kò gbọ . "Mo ti ní kí ọmọ mi má ṣe wá sí Ado Ekiti àmọ́ kò gbọ ọrọ si mi lẹ́nu. Ní báyìí tó sì ti dé sí Ado, ó gbọ́dọ̀ ṣe ayẹwo àrùn Coronavirus ni, kò to dára pọ mọ wa." Babafemi ni kí òun to gba ọmọ òun sínú ilé, yóò kọ́kọ́ lo ọjọ́ mẹ́rìnlá na ni ibùdó iyasọtọ nítorí òun kò leè fi ẹbí òun sínú ewu àrùn Covid-19. Baba náà ni ó yẹ kí òun fi ọ̀rọ̀ obìnrin oloyun tó wà sì Èkìtì láti ìlú Èkó ṣe arikọgbọn, ẹni tó ko àrùn Coronavirus wá Ekiti láti Eko. Awọn to ji Komisana eto ọgbin gbe ni ipinlẹ Ekiti ọgbẹni Folorunsho Olabode gbe ti beere ọgbọn miliọnu naira gẹgẹ bi owo tawọn yoo gba ki wọn to tu silẹ. Ni irọlẹ ọjọ Aiku lawọn ajinigbe yi da ọkọ rẹ lọna ni opopona Isan Iludun ni Ekiti. Wọn ji Kọmisana naa ati eeyan kan ti wọn jọ wa ninu ọkọ gbe ti wọn si tun yinbọn pa Kansilọ nijọba ibilẹ Ilejemeje kan ti wọn jọ wa ninu ọkọ naa. Ninu ohun ta ri gbọ ninu awọn iwe iroyin ilẹ Naijiria,eeyan kan ninu mọlẹbi Kọmisana sọ fun awọn akọroyin ni iAdo Ekiti lọjọ Aje pe awọn ajinigbe naa ti pe awọn lori ago ti wọn si ti beere owo ẹmi ọgbọn miliọnu naira. Eni ta n wi yi sọ pe ninu ibẹrubojo ni awọn eeyan ilu Kọmisana naa ti se Iye wa ti wọn si n rawọ ẹbẹ si Gomina la ti sa gbogbo agbara lati ri pe wọn doola ẹmi ọmọ awọn. ''A n bẹ Gomina Kayode Fayemi ati awọn agbofinro lati sa gbogbo agbara wọ́n ki wọn ba le doola rẹ'' Ewẹ alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekoto Sunday Abutu to tẹpẹlẹmọ ipinu ajọ naa lati wa Kọmisana naa jade ni awọn ko mọ si owo ẹmi tawọn ajinigbe naa n beere. ''A ko mọ si pe awọn ajinigbe naa n beere owo ki wọn to tusilẹ.Wọn o ti sọ fun wa'' Bakanna ni ọkan lara awọn ọmọ ile asofin nipinlẹ Ekiti ti ni ara ohun ti Coronavirus da silẹ ni ijingbe yi jẹ nitori ohun ni ko jẹ ki wọn se ifilọlẹ ikọ alaabo Amọtẹkun lasiko. Tope Ogunleye to n soju ẹkun idibo Ilejemeje ni ''inu mi ko dun si gbogbo ohun to n sẹlẹ yi.Awọn ọdaran yi ko sẹsẹ ma sọsẹ laaye ibi ti wọn ti ji Kọmisana gbe.Mo mọ wi pe Gomina Fayemi ko fi ọrọ yi sere rara'' Ogunleye ni nigba ti Covid-19 yoo ba fi kasẹ nilẹ, gomina yoo raaye lati se ifilọlẹ ikọ Amọtẹkun. O sọ pe awọn eeyan awọn to mọ tibu toro agbegbe naa ni yoo wa nibẹ ti wọn yoo si le awọn ọdaran kuro ni ipinlẹ Ekiti. Ina nla kan tun sọ lọsan oni lagbegbe college Road Road, Abatan Ọgba ni ilu Eko. Titi di asiko ti a fi n ṣa iroyin yii jọ, ko tii si ẹni lee sọ ohun gan ni pato to fa ijamba ina naa. Ileepo NNPC to wa ni agbegbe naa ni ina naa ti sọ eyi ti o jo ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye. Gbajumọ akọroyin àti olóṣèlú kan, Dele Momoodu tí woye pe o ṣeé ṣe kí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà wo, tí àwọn aráàlú bá fi bínú lórí àfikún igbele àrùn Coronavirus. Dele Momoodu, lásìkò to ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé, kí ìjọba tí àwọn èèyàn mọle kọ ní ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tó wà láti dènà àrùn Coronavirus. "Tí ẹ bá wo orílẹ̀ èdè Ghana, ó ní ọ̀nà tí ìjọba ń gba láti dènà ifarakinra. Yorùbá si ní ebi kii wọnú, kí ọ̀rọ̀ miran wọ, ebi sì ni ìṣòro ni orílẹ̀ èdè wa". "Ilẹ̀ Nàìjíríà kii se UK, Amẹ́ríkà àti Faranse. Kò sí oúnjẹ, kò sì iná, ẹ wá fẹ tí àwọn èèyàn mọle, kò leè ṣeé ṣe, èmi kò sì mọ bí ijọba wá ṣe fẹ ṣe. " Bákan náà ni Dele Momoodu koro ojú sì bí ìjọba ṣe kó owó sórí tabili, tí wọn sì ń pín bíi ìgbà tí wọn ń pín àkàrà, èmi kò sì tíì rí èèyàn tó ní òun ti rí owó náà gbà. "A ti pariwo títí fún ìjọba, wọn kò gbọ, Nàìjíríà kò sì ní àkọsílẹ̀ gidi. Kí ló dé tí ìjọba kò ṣe lọ nọ́mbà àsùnwọ̀n owó ni banki láti fi pín owó náà àti pé ọna wo ni wọn gba mọ àwọn aláìní." Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí akojọpọ esi tí ileesẹ tó ń gbógun ti àrùn nilẹ yìí, Momoodu ni Naijiria kò ní àkọsílẹ̀ tó dára lórí iye èèyàn tó ní Coronavirus ni Naijiria, bẹ́ẹ̀ sì ni ọpọ àwọn èèyàn tó wà nibẹ lo ń fẹ́ jẹun láti ara àìsàn náà. Lórí erongba aṣáájú ẹgbẹ́ APC àti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Eko tẹ́lẹ̀, Senato Bola Hammed Tinubu láti di aarẹ Naijiria lọ́dún 2023, Momoodu ni lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, Tinubu sì lo kajuẹ julọ láti darí orílẹ̀ èdè yìí. O ṣàlàyé pé lóòótọ́ ni Tinubu kò fẹ́ lórí bí àwọn èèyàn ṣe ń pariwo rẹ pé kò wá díje nítorí ó ti ìgbésẹ ọhun bíi ìwà ọyaju sì aarẹ Buhari to wa lori aleefa, nígbà tí kò tíì parí ṣáá isejọba rẹ. Momoodu ni "Ọpọlọpọ owó tí awọn eniyan kan ní Tinubu kò yìí, kii na fún ara rẹ nìkan nítorí pé ó ní ojú àánú pupọ, tó sì máa ń rán aráàlú lọ́wọ́,koda tipátipá lọ máa ń fi jẹun." "Bí APC ba fà Olóye Tinubu silẹ láti díje fún ipò Ààrẹ Naijiria, ó dá mi lójú pé, ó tó gbangba sùn lọyẹ, òun ni yóò mókè laarin awọn oludije yòókù nítorí pé ó kúnjú òṣùwọ̀n, tí yóò sì soro kò tó má di aarẹ Nàìjíríà." Momoodu tún woye pe ìlànà wiwo ọ̀rọ̀ ẹṣin, ẹ̀yà àti owó láti fà oludije kalẹ ni Naijiria kò bójú mú nítorí ẹni tí kò bá ní owó láti pin tàbí jẹ́ ẹlẹ́ṣin tó kàn láti díje, wọn kò ní ṣe atileyin gùn onitohun. Titi di ọjọ Kejila, oṣu Kinni, ọdun 2020, orilẹ-ede China nikan lo tii ni awọn to ni aarun coronavirus. Sugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ kẹtala, oṣu Kínní, aarun naa ti di ti gbogbo agbaye, nitori pe orilẹ-ede bi Thailand, Japan, South Korea àti America ṣe bẹ̀rẹ̀ si i ni akọsilẹ ti wọn naa. Lẹyin naa ni aarun naa bẹ̀rẹ̀ si tàn de awọn orilẹ-ede yooku, to fi mọ Africa. Lọwọ-lọwọ, o ti to miliọnu meji eniyan to ti ni aarun naa. Itan Iṣẹlẹ COVID 19 ní Naijiria: Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ni Naijiria kọkọ ni akọsilẹ aarun naa, lẹyin ti ọmọ orilẹ-ede Italy kan ni i.Lẹyin naa ni akọsilẹ ẹni keji waye lọjọ kẹsàn-án, oṣu Kẹta. Ọmọ Naijiria ni.Lẹyin eyi ni awọn to ni n pọ si. Níbo ni ọrọ coronavirus de duro bayii ni Naijiria? Lọwọ lọwọ, eniyan irinwo ati meje ni ajọ to n dena aarun ni Naijiria, NCDC, sọ pe o ni coronavirus. Awọn ipinlẹ ti aarun naa ti de ni Lagos Abuja Osun Edo Oyo Bauchi Akwa Ibom Kaduna Ogun Enugu Ekiti Kwara Rivers Benue Ondo Delta Katsina Anambra Niger Kano Apapọ wọn jẹ: mọkandinlogun ati Abuja to jẹ olu ilu Naijiria. Àwọn ipinlẹ ti Covid-19 ko ti i de ni NaijiriaBi aarun yii ṣe n tankalẹ to naa ni a ṣi ni awọn ipinlẹ ti ko tii de ni Naijiria. Ipinlẹ mẹrindinlogun ni coronavirus ko ti i de ni Naijiria naa niwọnyii:.Gombe Adamawa Plateau Borno Ebonyi Cross River Sokoto Kebbi Imo Bayelsa Taraba Kogi Nasarawa Zamfara Yobe Jigawa Igbesẹ wo ni wọn n gbe lati ri pe ajakalẹ aarun yii ko de ipinlẹ wọn? Lootọ ni coronavirus ko ti i de awọn ipinlẹ naa, sugbọn lati igba to ti de Naijiria ni diẹ lara wọn ti gbe awọn igbesẹ lati ri i daju pe ko wọ ipinlẹ wọn, àti ọna ti wọn yoo gba koju rẹ to ba ṣèèṣì wọle. Ipinlẹ Borno gbé igbimọ amusẹya kalẹ lati sisẹ pẹlu awọn ileesẹ aladani, ile ijọsin ati awọn ajọ ti kii se ti jọba lati koju aarun naa, to ba fi le wọ ibẹ. Lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ipinlẹ Kebbi kede pe ki gbogbo ileewe o wa ni titi pa.Ipinlẹ Ebonyi naa fi ofin de ipejọpọ ọpọ eniyan, lọjọ kẹtalelogun, ọsu kẹta. Bakan naa ni ipinlẹ Bayelsa ati Imo kede lọjọ kẹrindinlọgbọn pe ki awọn ileewe di titi pa, wọn si tun fi ofin de ipejọpọ ọpọ eniyan to ba le ni àádọ́ta. Ni ti ipinlẹ Abia, o ti gbogbo ẹnu ibode ipinlẹ naa pa fun ọsẹ mẹrin, o si tun pasẹ pe ki gbogbo araalu o joko sile. Àwọn ile itaja oúnjẹ àti òògùn nìkan ni ofin naa yọ silẹ. Ijọba ipinlẹ Cross River fi ofin de ipejọpọ nile ijọsin.Kebbi àti Taraba ko ti ẹ gba ki ẹnikẹni wọle si tabi jade kuro ni ipinlẹ naa. Niṣe lo yẹ ki onikaluku maa fọwọ wọn loorekoore ki wọn si tẹle gbogbo imọran ajọ WHO lori didẹkun itankalẹ ajakalẹ aarun coronavirus laisko yii. ''O lè kó coronavirus nípa ṣíṣe eré ìdárayá, ẹ gbélé yín lásìkò yìí,''- onímọ̀ ètò ìlera Coronavirus in Nigeria: ''Èèyàn lè kó coronavirus nípa ṣíṣe eré ìdárayá, ẹ gbélé yín lásìkò yìí,'' Onimọ nipa eto ilera, Dokita Ikubese Wilson ṣe atupalẹ bi eeya ti le ko aarun coronavirus nipasẹ ṣiṣe ere idaraya. Ilana ijinasiraẹni jẹ ọkan gboogi lara awọn igbesẹ ti ajọ eto ilera agbaye, WHO gbe kalẹ gẹgẹ bi ara ọna ti a le gba dena itankalẹ aarun Coronavirus. Àwọn Ìpínlẹ̀ tí coronavirus kò tíì dé ní Nàìjíríà, àti ìgbésẹ̀ tí wọ́n ń gbé láti dènà rẹ̀ Nitorinaa, ko jẹ iyalẹnu pe ilana ijinasiraẹni yii wa lara awọn igbesẹ ti ijọba lẹkajẹka gbogbo ni orilẹede Naijiria tẹnpẹlẹ mọ julọ gẹgẹ bi ọna lati din ọwọja aarun naa ku nilẹ yii. Lati fi idi ilana naa mulẹ, awọn ijọba ipinlẹ bii Eko tilẹ fi ofin gbee lẹyin, ofin yii si wa lara eyi ti wọn gbe kalẹ ni ile ẹjọ lati fi gbajugbaja oṣere sinima, Funkẹ Akindele ati ọkọ rẹ j'ofin ni ọjọ Aje. Amọṣa, ohun to wa n ṣe ọpọ ni haahinin bayii ni bi awọn eeyan ko ṣe karamasiki ilana yii. Bi o tilẹ jẹ wi pe ijọba apapọ paṣẹ konile-o-gbele lawọn ipinlẹ kan bii Eko, Ogun ati Abuja, ohun ti o n farahan bayii paapaa lori ayelujara ni pe ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn ko fẹ ki jijoko pa sile o sọ awọn di nnkan miran ti wọn si ti bẹrẹ ere idaraya kaakiri lati fi na eegun ati ara wọn. Amọṣa o, nipasẹ ṣiṣe eyi, ọpọ wọn lo ti n darapọ mọ ibi ti ọpọ ero wa, ti wọn si ti n t'ipasẹ bẹẹ fi ara wọn sinu ewu ati ko arun Coronavirus. Nibayii ọpọ aworan eyi lo si ti lu ori ayelujara pa. Ọpọ igba ni igbesẹ ijọba lo ti ba oniruru iha araalu pade. Arabinrin kan to ni ki a fi orukọ bo oun laṣiri ṣalaye pe ni agbegbe ti oun n gbe ni ilu Eko ni oun ti maa n ṣe ere idaraya lati na eegun ati ara oun. O ni nigba ti oun yoo fi jade ni ọjọ Aje, 'igboro ti daru' loun lee fi we nitori iye awọn to wa nigboro lati ṣe ere idaraya. O ni eyi lo mu ki oun pinnu lati dawọ duro naa. Ni aipẹ yii ni awọn olujọsin ni mọṣalaṣi kan ni ilu Eko kọlu awọn oṣiṣẹ ikọ amuṣẹya ti ijọba gbe kalẹ ti wọn wa kan si wọn pe ki wọn pa ofin naa mọ nitori nṣe ni ileejọsin naa kun bamubamu fun awọn to wa kirun. Njẹ eeyan le ko aarun coronavirus nipa ṣiṣe ere idaraya? Onimọ nipa eto ilera, Dokita Ikubese Wilson ṣe atupalẹ bi eeya ti le ko aarun coronavirus nipasẹ ṣiṣe ere idaraya. Dokita Wilson ṣalaye pe o ṣeeṣe ki eeyan ti ipasẹ ere idaraya ko aarun covid-19 nitori sisun mọ ẹni to ni aarun naa lara. Bakan naa lo sọ pe kokoro aarun covid-19 le wa laaye yala lara ohun elo ere idaraya ti ẹni to ni aarun naa ba ti lo, nitorinaa ''asiko yii ko dara fun ṣiṣe ere idaraya nitori ewu to wa nibẹ pọ.'' Dokita Wilson tun ṣalaye pe ti eeyan ba n ṣe ere idaraya, eemi ẹni naa maa pọ si, bakan naa ni afẹfẹ to n jade lati inu ẹdọ foro naa yoo pọ si. ''Ti ẹni to n ṣe ere idaraya ba mi, eemi naa yoo maa jade leralera, ti ẹni naa ba si ni aarun coronavirus, ẹlomiiran ti wọn jọ n ṣe ere iadaraya le ko aarun naa lara rẹ,'' Dokita Wilson lo woye bẹẹ. O rọ awọn eeyan lati maa ṣe ere idaraya ninu ile wọn lasiko ti ofin konle-o-gbele wa lode nitori ewu to wa ninu ṣiṣe ere idaraya loju popo tabi ni gbọngan ere idaraya lasiko yii. O ni fifi ẹmi ẹlomiiran wewu ni ṣiṣe ere idaraya pẹlu awọn mii tumọ sii lasiko yii. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-52202750 |
3politics
| Ewú ńlá ni Peter Obi àti Kwankwaso jẹ́ fún PDP ní ìdìbò 2023 – Fayose | Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose, ti sapejuwe awọn oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati NNPP gẹgẹ ewu nla fun aṣeyori ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo lọdun 2023. Fayose, nigba to n sọrọ lori tẹlifisan Channels salaye pe Obi ati Kwankwaso ni agbara lati le ṣe idiwọ fun ẹgbẹ oṣelu ẹgbẹ PDP lati bori ninu eto idibo aarẹ. Gẹgẹ bii o ṣe sọ , o ni oun ko ni igbagbọ pe Obi le ri ida mẹdọgbọn ibo kojọ ninu eto to n bọ ati pe ko le bori ibo apa guusu iwọ oorun ati guusu ila oorun orilẹede Naijria. “Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni mii, olori ni mi sugbọn mo ti n sọ fun tin tipẹ, a ko gbọdọ ma otitọ ọrọ. Ewu ni Obi jẹ fun wa sugbọn n ko ni igbagbọ pe yoo ni ida mẹdọgbọn ibo awọn ipinlẹ. N ko tako Obi, mo nifẹ rẹ, olori to daa ni. “Ẹ jẹ ki sọ fun yin, aarun jẹjẹrẹ ni Obi jẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP, ko si aniani nibẹ. E jẹ ki salaye nkan fun yin, ni guusu iwọ oorun, awọn eyan le ma fẹ gbọ otitọ ọrọ sugbọn n ko ri bii ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe fẹ bori ibo ni apa ibi. “Ẹni to ba tan wa, ko tẹsiwaju. Koda n ko ri ibi a ṣe le bori ni guusu ila oorun orilẹede yii pẹlu. O ni sugbọn oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NNPP, eyiu Rabiu Kwankwaso ni agbara lati mu inira ba bibori ni apa ariwa ila oorun bakan an. “Ni apa aarin ariwa, ko si isẹ pupọ lati ṣe nitori oludije PDP ati APC ko wa lati ibẹ sugbọn a ko gbọdọ gba gbe Kwankwaso, aarun jẹjẹrẹ miiran. Fayose salaye siwaju pe anfani wa fun ẹgbẹ oṣelu PDP ba le fọwọsowọpọ pẹlu Peter Obi ti Labour Party, ki wọn si tun bu omi pa awọ pẹlu gomin ipinlẹ Rivers, Nelson Wike. O ni igbesẹ yii yoo fun ẹgbẹ oṣelu PDP ni ọpọlọpọ anfani lati bori ninu eto idibo lọdun 2023. “Fifi ọwọ sowọpọ pẹlu Obi jẹ nkan to da pupọ, ti wọn ba si omi pa awọ to wa laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ati Gomina Nelson Wike ti ipinlẹ Rivers.” Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayodele fayose ti sọ pe oun ko ni sọrọ kobakungbe si oludije fun ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu. Fayose, to jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle, Channels. O ni “Jẹ ki n sọ fun ọ, ti awọn eeyan ba n reti ki n sọrọ kobakungbe nipa Tinubu lati fi han pe mi o ṣatilẹyin fun,mi o ni ṣe bẹẹ rara.” Fayoṣe ni, bo tilẹ jẹ pe awọn gomina atawọn oloṣelu kan ni iha Ariwa ni ariyanjiyan pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari, wọn kii sọrọ kobakungbe si. Gẹgẹ bii ohun to sọ, Tinubu jẹ ọkan lara awọn aṣaju ilẹ Yoruba, nitori naa oun ko ni maa sọrọ abuku si nitori wọn ko si ninu ẹgbẹ kan naa. Gomina Ekiti tẹlẹri naa ṣalaye pe oun ko ni bu Tinubu lailai. O ni “To ba jẹ pe ọna kan ti mo le fi han gbogbon eeyan pe ọta Tinubu ni mi ni ki n maa bu gẹgẹ bii ọmọ Yoruba, mi o ni ṣe bẹẹ lailai.” “Ọjọ ori Atiku Abubakar ati Bola Tinu ti le ni aadọrin ọdun, ki lo de ti awọn mejeji fi n joko papaọ lati jiroro ti wọn ko si maa yọ ada si ara wọn? Ẹ yọ mi kuro lara awọn ti yoo maa bu Tinubu.” “Mi o ni bu Atiku.... bẹẹ naa ni mi o ni bu Tinubu.” Fayose sọ pe lootọ ni ipo Aarẹ tọ si iha Guusu Naijiria ni bayii ti Buhari to wa lati Ariwa yoo pari saa rẹ to lẹyin ọdun mẹjọ. O pari ọrọ rẹ pe oun yoo ṣiṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP bo tilẹ jẹ pe aarin ẹgbẹ ọhun ko gun rege. | Ewú ńlá ni Peter Obi àti Kwankwaso jẹ́ fún PDP ní ìdìbò 2023 – Fayose Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose, ti sapejuwe awọn oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati NNPP gẹgẹ ewu nla fun aṣeyori ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo lọdun 2023. Fayose, nigba to n sọrọ lori tẹlifisan Channels salaye pe Obi ati Kwankwaso ni agbara lati le ṣe idiwọ fun ẹgbẹ oṣelu ẹgbẹ PDP lati bori ninu eto idibo aarẹ. Gẹgẹ bii o ṣe sọ , o ni oun ko ni igbagbọ pe Obi le ri ida mẹdọgbọn ibo kojọ ninu eto to n bọ ati pe ko le bori ibo apa guusu iwọ oorun ati guusu ila oorun orilẹede Naijria. “Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni mii, olori ni mi sugbọn mo ti n sọ fun tin tipẹ, a ko gbọdọ ma otitọ ọrọ. Ewu ni Obi jẹ fun wa sugbọn n ko ni igbagbọ pe yoo ni ida mẹdọgbọn ibo awọn ipinlẹ. N ko tako Obi, mo nifẹ rẹ, olori to daa ni. “Ẹ jẹ ki sọ fun yin, aarun jẹjẹrẹ ni Obi jẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP, ko si aniani nibẹ. E jẹ ki salaye nkan fun yin, ni guusu iwọ oorun, awọn eyan le ma fẹ gbọ otitọ ọrọ sugbọn n ko ri bii ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe fẹ bori ibo ni apa ibi. “Ẹni to ba tan wa, ko tẹsiwaju. Koda n ko ri ibi a ṣe le bori ni guusu ila oorun orilẹede yii pẹlu. O ni sugbọn oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NNPP, eyiu Rabiu Kwankwaso ni agbara lati mu inira ba bibori ni apa ariwa ila oorun bakan an. “Ni apa aarin ariwa, ko si isẹ pupọ lati ṣe nitori oludije PDP ati APC ko wa lati ibẹ sugbọn a ko gbọdọ gba gbe Kwankwaso, aarun jẹjẹrẹ miiran. Fayose salaye siwaju pe anfani wa fun ẹgbẹ oṣelu PDP ba le fọwọsowọpọ pẹlu Peter Obi ti Labour Party, ki wọn si tun bu omi pa awọ pẹlu gomin ipinlẹ Rivers, Nelson Wike. O ni igbesẹ yii yoo fun ẹgbẹ oṣelu PDP ni ọpọlọpọ anfani lati bori ninu eto idibo lọdun 2023. “Fifi ọwọ sowọpọ pẹlu Obi jẹ nkan to da pupọ, ti wọn ba si omi pa awọ to wa laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ati Gomina Nelson Wike ti ipinlẹ Rivers.” Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayodele fayose ti sọ pe oun ko ni sọrọ kobakungbe si oludije fun ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu. Fayose, to jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle, Channels. O ni “Jẹ ki n sọ fun ọ, ti awọn eeyan ba n reti ki n sọrọ kobakungbe nipa Tinubu lati fi han pe mi o ṣatilẹyin fun,mi o ni ṣe bẹẹ rara.” Fayoṣe ni, bo tilẹ jẹ pe awọn gomina atawọn oloṣelu kan ni iha Ariwa ni ariyanjiyan pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari, wọn kii sọrọ kobakungbe si. Gẹgẹ bii ohun to sọ, Tinubu jẹ ọkan lara awọn aṣaju ilẹ Yoruba, nitori naa oun ko ni maa sọrọ abuku si nitori wọn ko si ninu ẹgbẹ kan naa. Gomina Ekiti tẹlẹri naa ṣalaye pe oun ko ni bu Tinubu lailai. O ni “To ba jẹ pe ọna kan ti mo le fi han gbogbon eeyan pe ọta Tinubu ni mi ni ki n maa bu gẹgẹ bii ọmọ Yoruba, mi o ni ṣe bẹẹ lailai.” “Ọjọ ori Atiku Abubakar ati Bola Tinu ti le ni aadọrin ọdun, ki lo de ti awọn mejeji fi n joko papaọ lati jiroro ti wọn ko si maa yọ ada si ara wọn? Ẹ yọ mi kuro lara awọn ti yoo maa bu Tinubu.” “Mi o ni bu Atiku.... bẹẹ naa ni mi o ni bu Tinubu.” Fayose sọ pe lootọ ni ipo Aarẹ tọ si iha Guusu Naijiria ni bayii ti Buhari to wa lati Ariwa yoo pari saa rẹ to lẹyin ọdun mẹjọ. O pari ọrọ rẹ pe oun yoo ṣiṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP bo tilẹ jẹ pe aarin ẹgbẹ ọhun ko gun rege. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cj7zlvk42z9o |
1entertainment
| Kwam 1's new wife: Emmanuella Ropo di aya Kwam 1, bó ṣe lọ rèé | Lẹyin ọdun mẹta ti gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde ti ọpọ mọ si Kwam 1 fẹ iyawo rẹ kekere, Titi Masha ni Ijebu-Ode, agogo igbeyawo tun ti dun laarin olorin naa ati ọmọ ẹlẹ kan, Emmanuella Ropo. Lọjọru ọsẹ ni igbeyawo Kwam 1 waye niluu Abeokuta pẹlu apọnbeporẹ arẹwa obinrin, Aderopo Emmanuella ti gbogbo ilu mi titi. Ropo jẹ ẹni to ti le ni Ogoji ọdun lọjọ ori nigba ti Wasiu Ayinde jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgọta to si ti ni ọmọ to le ni ogoji latọdọ ọpọlọpọ obinrin. Wọ́n ti ń bèrè lọ́wọ́ abúrò ọkọ mi pé èlò ni wọ́n fẹ́ gbà, ẹ ṣàánú wa o! - Ìyàwó Timothy tó kú sí Hilton Hotel Osun figbe ta Wọ́n lù mí bíi ẹní máa kú, wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn nílé Princess kí n tó dé àgọ́ ọlọ́pàá - Baba Ijesha Ìkúnlẹ̀ abiyamọ ò! Wo bí arábìnrin yìí ṣé bínú dá omi gbígbóná s'ará ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ Pásítọ̀ onísọjí tó fí ipá bá olóyún oṣù mẹ́jọ sùn ní Ondo, ohun tí a mọ̀ rèé Amọṣa kii ṣe pe o fẹ gbogbo wọn sile. Iyawo ti wọn mọ mọ Kwam 1 ju ni Yewande to n gbe ni Canada ti wọn si ni ọmọ marun papọ. Taa ni arẹ̀wà obìnrin, Emmanuella Ropo tí ìròyìn n sọ pé òun ni ìyàwò K1 tuntun? Kwam 1 dá àwọn tó ń wọ́ ọ tuurutu nílẹ̀ pé ó jẹ́ gbèsè dollar iṣẹ́ orin kan l'Amẹ́rika Ṣé lóòtọ́ ni Alaafin Ọyọ ti fẹ́ olorì tuntun láti ẹ̀yà Igbo? Ẹ wo ǹkan tí a mọ̀ nípa rẹ̀ Wasiu ko fi bo rara gẹgẹ bo ṣe maa n pe ara rẹ ni alaya pupọ eyi ti oloyinbo n pe ni Polygamist to si ni oun ko tii de ipo ti Fela Anikulapo gbajugbaja olorin to ti d'oloogbe to ni akọsilẹ iyawo mẹtadinlọgbọn. Oṣu to kọja ni iroyin brẹ si ni ta si awọn eeyan leti pe Kwam 1 tun ti fẹ ṣe iyawo pẹlu ẹlẹ tuntun yii. Koda o fi orin kan sori ayelujara ninu eyi to ti n pe e ni "Ajike Okin ati Neulla Ajike Mi". Emmanuella naa fi ọrọ ifẹ rẹ sita nipa igbeyawo naa to n gbadura fun ẹmi gigun ninu ifẹ ati idunu fun oun ati Kwam 1. Gbas-gbos ti ń wáyé ṣáájú ìdìbò sí ipò gómìnà Osun, kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàrín Aregbesola, Oyetola? Buhari ti sọ̀rọ̀ sókè lórí àbájáde ìwádìí EndSARS, ilẹ̀ Amẹ́ríkà sì ti fun lésì Àwọn alamí ìjọba kan ti wà láàrín àwa ajìjàgbara Yoruba Nation tó ń bínú pé Sunday Igboho ti ga ju àwọn lọ - Akintoye Ilééṣé ọlọ́pàá Osun tí mú Olùdarí ilé ìtura tí Akẹ́kòó fásìtì OAU ti dédé pòórá | Kwam 1's new wife: Emmanuella Ropo di aya Kwam 1, bó ṣe lọ rèé Lẹyin ọdun mẹta ti gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde ti ọpọ mọ si Kwam 1 fẹ iyawo rẹ kekere, Titi Masha ni Ijebu-Ode, agogo igbeyawo tun ti dun laarin olorin naa ati ọmọ ẹlẹ kan, Emmanuella Ropo. Lọjọru ọsẹ ni igbeyawo Kwam 1 waye niluu Abeokuta pẹlu apọnbeporẹ arẹwa obinrin, Aderopo Emmanuella ti gbogbo ilu mi titi. Ropo jẹ ẹni to ti le ni Ogoji ọdun lọjọ ori nigba ti Wasiu Ayinde jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgọta to si ti ni ọmọ to le ni ogoji latọdọ ọpọlọpọ obinrin. Wọ́n ti ń bèrè lọ́wọ́ abúrò ọkọ mi pé èlò ni wọ́n fẹ́ gbà, ẹ ṣàánú wa o! - Ìyàwó Timothy tó kú sí Hilton Hotel Osun figbe ta Wọ́n lù mí bíi ẹní máa kú, wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn nílé Princess kí n tó dé àgọ́ ọlọ́pàá - Baba Ijesha Ìkúnlẹ̀ abiyamọ ò! Wo bí arábìnrin yìí ṣé bínú dá omi gbígbóná s'ará ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ Pásítọ̀ onísọjí tó fí ipá bá olóyún oṣù mẹ́jọ sùn ní Ondo, ohun tí a mọ̀ rèé Amọṣa kii ṣe pe o fẹ gbogbo wọn sile. Iyawo ti wọn mọ mọ Kwam 1 ju ni Yewande to n gbe ni Canada ti wọn si ni ọmọ marun papọ. Taa ni arẹ̀wà obìnrin, Emmanuella Ropo tí ìròyìn n sọ pé òun ni ìyàwò K1 tuntun? Kwam 1 dá àwọn tó ń wọ́ ọ tuurutu nílẹ̀ pé ó jẹ́ gbèsè dollar iṣẹ́ orin kan l'Amẹ́rika Ṣé lóòtọ́ ni Alaafin Ọyọ ti fẹ́ olorì tuntun láti ẹ̀yà Igbo? Ẹ wo ǹkan tí a mọ̀ nípa rẹ̀ Wasiu ko fi bo rara gẹgẹ bo ṣe maa n pe ara rẹ ni alaya pupọ eyi ti oloyinbo n pe ni Polygamist to si ni oun ko tii de ipo ti Fela Anikulapo gbajugbaja olorin to ti d'oloogbe to ni akọsilẹ iyawo mẹtadinlọgbọn. Oṣu to kọja ni iroyin brẹ si ni ta si awọn eeyan leti pe Kwam 1 tun ti fẹ ṣe iyawo pẹlu ẹlẹ tuntun yii. Koda o fi orin kan sori ayelujara ninu eyi to ti n pe e ni "Ajike Okin ati Neulla Ajike Mi". Emmanuella naa fi ọrọ ifẹ rẹ sita nipa igbeyawo naa to n gbadura fun ẹmi gigun ninu ifẹ ati idunu fun oun ati Kwam 1. Gbas-gbos ti ń wáyé ṣáájú ìdìbò sí ipò gómìnà Osun, kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàrín Aregbesola, Oyetola? Buhari ti sọ̀rọ̀ sókè lórí àbájáde ìwádìí EndSARS, ilẹ̀ Amẹ́ríkà sì ti fun lésì Àwọn alamí ìjọba kan ti wà láàrín àwa ajìjàgbara Yoruba Nation tó ń bínú pé Sunday Igboho ti ga ju àwọn lọ - Akintoye Ilééṣé ọlọ́pàá Osun tí mú Olùdarí ilé ìtura tí Akẹ́kòó fásìtì OAU ti dédé pòórá | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-59337105 |
5sports
| Ikọ̀ Bayana Bayana ti South Africa ló gba Ife Ẹ̀yẹ WAFCON lẹ́yìn ìgbìyànjú ìgba mẹ́rin | Ikọ agbabọọlu obinrin ti South Africa, Bayana Bayana ti gba Ife Ẹyẹ Agbaye, WAFCON fun igba akọkọ lẹyin ti wọn na ikọ agbabọọlu Morocco ninu aṣekagba idije naa. Agbabọọlu obinrin Hildah Magaia lo ṣe moriya ninu idije naa lẹyin ti o ṣiṣẹ karakara ti ikọ South Africa fi bori ninu idije naa fun igba akọkọ lẹyin igbiyanju marun un. Ni saa akọkọ ifẹṣẹwọnṣẹ ni ikọ South Africa ti fakọyọ, ti ko si si ẹnikẹni ninu ikọ meji to gba bọọlu wọ inu awọn. Amọ Magaia ko gba fun wọn to si gba bọọlu wọ inu awọn ni iṣeju mẹta kọja ọgọta, eleyii to mu ki wọn saaju ninu idije naa. Lẹyin iṣẹju mẹjọ lẹyin naa ni wọn fi ọba le ti o si da mẹji ti ikọ Bayana Bayana fi bori. Ami ayo keji yii lo ji awọn ikọ Morocco ti wọn si tiraka lati fi ami ayo ẹyọkan naa sinu awọn. Arabinrin Ayane lo ṣiṣẹ to bẹẹ ti wọn fi pari erebọọlu naa. Igba mẹrin ti wọn ti kuna ni lọdun 2000, 2008, 2012 ati ọdun 2018 Ninu ọrọ rẹ, Balogun ikọ Bayana Bayana, Refiloe Jane ni irẹlẹ ni aṣeyọri naa jẹ fun wọn, ti inu awọn si dun daradara. O fikun un pe niiṣe ni oun bu ṣẹkun lẹyin ifẹṣẹwọnṣẹ naa, nitori awọn ṣiṣẹ karakara lati ri pe awọn gba Ife Ẹyẹ ti ọdun yii. Bakan naa ni akọnimọọgba ikọ naa, Desire Ellis ni inu ohun dun daradara ninu aṣeyọri yii nitori pe gbogbo igbiyanju wọn ni ọdun mejilelogun ṣẹyin lati bori gẹgẹ bi agbabọọlu lo jasi pabo. Iṣẹ takuntakun ni ikọ South-Africa ṣe pẹlu bi wọn ṣe n jijakadi pẹlu Morocco to jẹ ile ni wọn wa, ti wọn si ni awọn ololufẹ wọn biba to n ke fitafita fun wọn lati bori. | Ikọ̀ Bayana Bayana ti South Africa ló gba Ife Ẹ̀yẹ WAFCON lẹ́yìn ìgbìyànjú ìgba mẹ́rin Ikọ agbabọọlu obinrin ti South Africa, Bayana Bayana ti gba Ife Ẹyẹ Agbaye, WAFCON fun igba akọkọ lẹyin ti wọn na ikọ agbabọọlu Morocco ninu aṣekagba idije naa. Agbabọọlu obinrin Hildah Magaia lo ṣe moriya ninu idije naa lẹyin ti o ṣiṣẹ karakara ti ikọ South Africa fi bori ninu idije naa fun igba akọkọ lẹyin igbiyanju marun un. Ni saa akọkọ ifẹṣẹwọnṣẹ ni ikọ South Africa ti fakọyọ, ti ko si si ẹnikẹni ninu ikọ meji to gba bọọlu wọ inu awọn. Amọ Magaia ko gba fun wọn to si gba bọọlu wọ inu awọn ni iṣeju mẹta kọja ọgọta, eleyii to mu ki wọn saaju ninu idije naa. Lẹyin iṣẹju mẹjọ lẹyin naa ni wọn fi ọba le ti o si da mẹji ti ikọ Bayana Bayana fi bori. Ami ayo keji yii lo ji awọn ikọ Morocco ti wọn si tiraka lati fi ami ayo ẹyọkan naa sinu awọn. Arabinrin Ayane lo ṣiṣẹ to bẹẹ ti wọn fi pari erebọọlu naa. Igba mẹrin ti wọn ti kuna ni lọdun 2000, 2008, 2012 ati ọdun 2018 Ninu ọrọ rẹ, Balogun ikọ Bayana Bayana, Refiloe Jane ni irẹlẹ ni aṣeyọri naa jẹ fun wọn, ti inu awọn si dun daradara. O fikun un pe niiṣe ni oun bu ṣẹkun lẹyin ifẹṣẹwọnṣẹ naa, nitori awọn ṣiṣẹ karakara lati ri pe awọn gba Ife Ẹyẹ ti ọdun yii. Bakan naa ni akọnimọọgba ikọ naa, Desire Ellis ni inu ohun dun daradara ninu aṣeyọri yii nitori pe gbogbo igbiyanju wọn ni ọdun mejilelogun ṣẹyin lati bori gẹgẹ bi agbabọọlu lo jasi pabo. Iṣẹ takuntakun ni ikọ South-Africa ṣe pẹlu bi wọn ṣe n jijakadi pẹlu Morocco to jẹ ile ni wọn wa, ti wọn si ni awọn ololufẹ wọn biba to n ke fitafita fun wọn lati bori. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/c28gxzp70x9o |
3politics
| Seyi Makinde Defection: PDP ní ọ̀rọ̀ Fani-Kayode kò ṣé tẹ̀lé, asọ̀rọ̀ àná di bámíì ni | Ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Oyo ti ke s'awọn ọmọ Naijiria, lati fi ẹyinkule ọwọ da gbogbo ọrọ ti Fẹmi Fani-Kayọde ba sọ nu nitori atimaasebo rẹ ti fihan pe, ko duro soju kan ri, bẹẹ ni asọrọ ana di bamii ẹda ni. Bẹẹ ba gbagbe, Minisita ana feto irina ofurufu, Femi Fani-Kayọde lo ni oun lo ṣokunfa bi awọn gomina kan ṣe dara pọ mọ ẹgbẹ oselu APC ati pe laipẹ Gomina Makinde tipinlẹ Ọyọ naa pẹlu yoo fo fẹrẹ lọ si APC. Fani-Kayode sisọ loju ọrọ yii lasiko to n salaye idi to se kuro ninu ẹgbẹ PDP, rekọja lọ si APC laipẹ yii. Amọ nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun ti Fani-Kayode sọ yii, ẹgbẹ PDP ni lọwọ yii, awọn to n ko ba igbaye-gbadun araalu ni wọn n korajọ si ẹgbẹ oṣelu APC, nitorina ajegbodo to n wẹni kunra lọrọ Fani-Kayọde. Akọwe ipolongo f'ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Hakeem Ọlatunji woye pe niwọn igba ti Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ko ti lee kuro lẹgbẹ oṣelu APC, ko si ohun ti yoo yẹju Makinde pẹlu kuro lẹgbẹ oṣelu PDP. A ko fẹ Seyi Makinde ninu APC Oyo, yoo ba ọja jẹ fun wa ni - Abass Aleshinloye Bakan naa ninu ọrọ tirẹ, ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọyọ ni bi ẹlẹṣẹ to n lọ ṣọọsi tabi mọṣalaṣi fun irapada ọkan rẹ lọrọ Gomina Makinde yoo ri bo ba fẹ wa si ẹgbẹ oṣelu APC. Ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ ọyọ, Ọgbẹni Ayọdeji Alẹshinlọyẹ ṣalaye fun BBC News Yoruba pe iru wọn, a kii fa akoso ṣọọṣi tabi mọṣalaṣi ke wọn lọwọ. O fi kun un pe gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde yoo kan wa ba ọja jẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọyọ ni. Ẹgbẹ oṣelu APC ni bi gomina Makinde ba ti le fi ọwọ sibi tọwọ gbe to si ṣetan lati tẹle ilana ofin ẹgbẹ oṣelu APC mu. "Bo ba wa, a jẹ pe o ti di atunbi ni, ṣugbọn a ko ro pe yoo lee wa darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC." Ọgbẹni Ayọdeji Alẹshinlọyẹ to jẹ alaga ajọ awọn alaga kansu, ALGON tẹlẹ ni ipinlẹ Ọyọ ni ko saye fun un lati dije fun ipo gomina lẹgbẹ oselu APC bi o ba jẹ pe nitori atidije lo tori fẹ wa si ẹgbẹ naa. | Seyi Makinde Defection: PDP ní ọ̀rọ̀ Fani-Kayode kò ṣé tẹ̀lé, asọ̀rọ̀ àná di bámíì ni Ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Oyo ti ke s'awọn ọmọ Naijiria, lati fi ẹyinkule ọwọ da gbogbo ọrọ ti Fẹmi Fani-Kayọde ba sọ nu nitori atimaasebo rẹ ti fihan pe, ko duro soju kan ri, bẹẹ ni asọrọ ana di bamii ẹda ni. Bẹẹ ba gbagbe, Minisita ana feto irina ofurufu, Femi Fani-Kayọde lo ni oun lo ṣokunfa bi awọn gomina kan ṣe dara pọ mọ ẹgbẹ oselu APC ati pe laipẹ Gomina Makinde tipinlẹ Ọyọ naa pẹlu yoo fo fẹrẹ lọ si APC. Fani-Kayode sisọ loju ọrọ yii lasiko to n salaye idi to se kuro ninu ẹgbẹ PDP, rekọja lọ si APC laipẹ yii. Amọ nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun ti Fani-Kayode sọ yii, ẹgbẹ PDP ni lọwọ yii, awọn to n ko ba igbaye-gbadun araalu ni wọn n korajọ si ẹgbẹ oṣelu APC, nitorina ajegbodo to n wẹni kunra lọrọ Fani-Kayọde. Akọwe ipolongo f'ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Hakeem Ọlatunji woye pe niwọn igba ti Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ko ti lee kuro lẹgbẹ oṣelu APC, ko si ohun ti yoo yẹju Makinde pẹlu kuro lẹgbẹ oṣelu PDP. A ko fẹ Seyi Makinde ninu APC Oyo, yoo ba ọja jẹ fun wa ni - Abass Aleshinloye Bakan naa ninu ọrọ tirẹ, ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọyọ ni bi ẹlẹṣẹ to n lọ ṣọọsi tabi mọṣalaṣi fun irapada ọkan rẹ lọrọ Gomina Makinde yoo ri bo ba fẹ wa si ẹgbẹ oṣelu APC. Ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ ọyọ, Ọgbẹni Ayọdeji Alẹshinlọyẹ ṣalaye fun BBC News Yoruba pe iru wọn, a kii fa akoso ṣọọṣi tabi mọṣalaṣi ke wọn lọwọ. O fi kun un pe gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde yoo kan wa ba ọja jẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọyọ ni. Ẹgbẹ oṣelu APC ni bi gomina Makinde ba ti le fi ọwọ sibi tọwọ gbe to si ṣetan lati tẹle ilana ofin ẹgbẹ oṣelu APC mu. "Bo ba wa, a jẹ pe o ti di atunbi ni, ṣugbọn a ko ro pe yoo lee wa darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC." Ọgbẹni Ayọdeji Alẹshinlọyẹ to jẹ alaga ajọ awọn alaga kansu, ALGON tẹlẹ ni ipinlẹ Ọyọ ni ko saye fun un lati dije fun ipo gomina lẹgbẹ oselu APC bi o ba jẹ pe nitori atidije lo tori fẹ wa si ẹgbẹ naa. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58627029 |
4religion
| Shiite: Àwa kọ́ la yìnbọn pa ọ̀gá ọlọ́pàá àti akọ̀ròyìn | Ẹgbẹ musulumi Shiite, Islamic Movement in Nigeria, ti sọ pe, awọn kọ lo ṣeku pa ọga ọlọpaa, Usman Musa ati akọroyin ileeṣẹ Channels. Umar Usman ati Precious Owolabi ni wọn tẹri gbaṣọ ninu ikọlu ọlọpaa ati ẹgbẹ Shiite, nigba ti wọn n ṣe iwọde l'Abuja lọjọ Aje. Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Ibrahim Musa ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Iṣẹgun ṣalaye pe, ọta ibọn awọn ọlọpaa lo ba awọn mejeeji nitori awọn ẹgbẹ Shiite kii lo ibọn tabi ohun ija oloro kankan. O ni ko ṣeeṣe ko jẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite to n ṣe iwọde lo yinbọn pa awọn mejeeji. Aarẹ ẹgbẹ musulumi Shiite ni, ibanilorukọjẹ ni ọrọ ti ile iṣẹ ọlọpaa sọ pe Shiite lo ṣekupa ọga ọlọpaa Musa ati Owolabi. Ọgbẹni Musa ṣalaye pe, pẹlẹ kutu ni iwọde awọn n lọ ko to di pe awọn ọlọpaa da gbogbo rẹ ru. Lakotan, ẹgbẹ Shiite kẹdun pẹlu awọn ẹbi awọn to ku ninu ikọlu ọjọ Aje papaajulọ ẹbi ọga ọlọpaa ati oniroyin to ṣagbako iku ojiji ninu iṣẹlẹ ọhun. Ìdí ti a fi kọ̀ láti fi El-ZakZakky sílẹ̀ -Ileeṣẹ Aarẹ Buhari Ìdí ti a fi kọ̀ láti fi El-ZakZakky sílẹ̀ gẹgẹ bi ilé ẹjọ ṣe paṣẹ rẹ - Ileeṣẹ Aarẹ. Ogbẹni Femi Adesina to jẹ oludamọran fun aarẹ Mohammadu Buhari lori ọrọ iroyin ni kii ṣe pe ijọba fẹ tako aṣẹ ofin ile ẹjọ rara. O ni ijọba Buhari gbà pé o ni idi ti Adajọ Abubakar Malami (SAN) N3.5 mílíọ̀nù lórí El-Zakzaky, kíni àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sọ?ṣe fi paṣẹ pe ki wọn tu olori ẹsin Islam Shiite silẹỌ̀pọ̀ èèyàn farapa nínú ìwọ́de Shiite. Femi Adesina ni nitootọ ni o jẹ pe Adajọ agba ni Naijiria to paṣẹ itusilẹ El Zakzakky ati aya rẹ kuro ninu tubu ṣe eyi gẹgẹ bii agbara ofin ni. O ni koko pataki ni pe ti adajọ ba dajọ, aaye wa lati pe idajọ naa ninu ẹjọ kotẹmilọrun bi o ti yẹ. Femi Adesina ni kete ti wọn ba ti ni ki eeyan gba oniduro ninu ẹjọ ṣugbọn ti igbẹjọ kotẹmilọrun ba dide ni ofin ti faye gba pe ki wọn ṣi fi ẹni naa si ahamọ titi yoo fi yanju. O ni oun ko mọ ofin ni kikun ṣugbọn nkan kan ti o da oun loju ninu ifọrọwerọ naa ni pe ijọba ti gbe ẹjọ kotẹmilọrun lọ sile ẹjọ agba ni ipinlẹ Kaduna. Femi Adesina parọwa fawọn olujọsin Shiite pe ki wọn ni suuru nitori ọjọ Aje to m bọ nigbẹjọ yoo waye nile ẹjọ ni Kaduna. Agbẹnusọ fun aarẹ Buhari gboriyin fawọn agbofinro Naijiria pe wọn gbiyanju lasiko iwọde awọn ijọ Shiite to wyae ni Abuja. Iwọde yii lo mu ẹmi opolopo eeyna lọ ati ti agunbanirọ Channels kan ati ọga agba ọlọpaa kan. O ni kani awọn ọlọpaa sọ̀kò ẹyẹ ihuwasi awọn Shiite nibi iwọde yẹn nipa yinyin ibọn ni, ọpọ ẹmi ko ba tun sọnu sii. Femi Adesina ni ẹmi ọga ọlọpaa to sọnu sinu iṣẹlẹ iwọde yii to eyi to n gba ẹbọ lọwọ awọn oluwọde ṣugbọn oun ki awọn agbofinro fun gbigba alaafia laaye lai nii fiṣe ohun gbogbo to ṣẹlẹ. | Shiite: Àwa kọ́ la yìnbọn pa ọ̀gá ọlọ́pàá àti akọ̀ròyìn Ẹgbẹ musulumi Shiite, Islamic Movement in Nigeria, ti sọ pe, awọn kọ lo ṣeku pa ọga ọlọpaa, Usman Musa ati akọroyin ileeṣẹ Channels. Umar Usman ati Precious Owolabi ni wọn tẹri gbaṣọ ninu ikọlu ọlọpaa ati ẹgbẹ Shiite, nigba ti wọn n ṣe iwọde l'Abuja lọjọ Aje. Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Ibrahim Musa ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Iṣẹgun ṣalaye pe, ọta ibọn awọn ọlọpaa lo ba awọn mejeeji nitori awọn ẹgbẹ Shiite kii lo ibọn tabi ohun ija oloro kankan. O ni ko ṣeeṣe ko jẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite to n ṣe iwọde lo yinbọn pa awọn mejeeji. Aarẹ ẹgbẹ musulumi Shiite ni, ibanilorukọjẹ ni ọrọ ti ile iṣẹ ọlọpaa sọ pe Shiite lo ṣekupa ọga ọlọpaa Musa ati Owolabi. Ọgbẹni Musa ṣalaye pe, pẹlẹ kutu ni iwọde awọn n lọ ko to di pe awọn ọlọpaa da gbogbo rẹ ru. Lakotan, ẹgbẹ Shiite kẹdun pẹlu awọn ẹbi awọn to ku ninu ikọlu ọjọ Aje papaajulọ ẹbi ọga ọlọpaa ati oniroyin to ṣagbako iku ojiji ninu iṣẹlẹ ọhun. Ìdí ti a fi kọ̀ láti fi El-ZakZakky sílẹ̀ -Ileeṣẹ Aarẹ Buhari Ìdí ti a fi kọ̀ láti fi El-ZakZakky sílẹ̀ gẹgẹ bi ilé ẹjọ ṣe paṣẹ rẹ - Ileeṣẹ Aarẹ. Ogbẹni Femi Adesina to jẹ oludamọran fun aarẹ Mohammadu Buhari lori ọrọ iroyin ni kii ṣe pe ijọba fẹ tako aṣẹ ofin ile ẹjọ rara. O ni ijọba Buhari gbà pé o ni idi ti Adajọ Abubakar Malami (SAN) N3.5 mílíọ̀nù lórí El-Zakzaky, kíni àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sọ?ṣe fi paṣẹ pe ki wọn tu olori ẹsin Islam Shiite silẹỌ̀pọ̀ èèyàn farapa nínú ìwọ́de Shiite. Femi Adesina ni nitootọ ni o jẹ pe Adajọ agba ni Naijiria to paṣẹ itusilẹ El Zakzakky ati aya rẹ kuro ninu tubu ṣe eyi gẹgẹ bii agbara ofin ni. O ni koko pataki ni pe ti adajọ ba dajọ, aaye wa lati pe idajọ naa ninu ẹjọ kotẹmilọrun bi o ti yẹ. Femi Adesina ni kete ti wọn ba ti ni ki eeyan gba oniduro ninu ẹjọ ṣugbọn ti igbẹjọ kotẹmilọrun ba dide ni ofin ti faye gba pe ki wọn ṣi fi ẹni naa si ahamọ titi yoo fi yanju. O ni oun ko mọ ofin ni kikun ṣugbọn nkan kan ti o da oun loju ninu ifọrọwerọ naa ni pe ijọba ti gbe ẹjọ kotẹmilọrun lọ sile ẹjọ agba ni ipinlẹ Kaduna. Femi Adesina parọwa fawọn olujọsin Shiite pe ki wọn ni suuru nitori ọjọ Aje to m bọ nigbẹjọ yoo waye nile ẹjọ ni Kaduna. Agbẹnusọ fun aarẹ Buhari gboriyin fawọn agbofinro Naijiria pe wọn gbiyanju lasiko iwọde awọn ijọ Shiite to wyae ni Abuja. Iwọde yii lo mu ẹmi opolopo eeyna lọ ati ti agunbanirọ Channels kan ati ọga agba ọlọpaa kan. O ni kani awọn ọlọpaa sọ̀kò ẹyẹ ihuwasi awọn Shiite nibi iwọde yẹn nipa yinyin ibọn ni, ọpọ ẹmi ko ba tun sọnu sii. Femi Adesina ni ẹmi ọga ọlọpaa to sọnu sinu iṣẹlẹ iwọde yii to eyi to n gba ẹbọ lọwọ awọn oluwọde ṣugbọn oun ki awọn agbofinro fun gbigba alaafia laaye lai nii fiṣe ohun gbogbo to ṣẹlẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/49081498 |
1entertainment
| Mr Macaroni, Taaooma, Woli Agba, Adeyemi Elesho sọrọ lórí ìpè láti ṣèpàdé pẹ̀lú ìgbákéjì ààrẹ Yemi Osinbajo | Awọn gbajugbaja apanilẹrin bii Debo Mr Macaroni, Taaooma, Woli Agba Ayo Ajewole ati Adeyemi Elesho to jẹ ọmọ agba oṣere, Elesho ti fi ọrọ sita lori ipade kan ti wọn pe wọn si pẹlu igbakeji aar Naijiria, Yemi Osinbajo eyi to di ariwo lori ayelujara lẹnu awọn ọdọ Naijiria. Maryam Apaokagi ti ọpọ mọ si Taaooma ti sọrọ pe oun tọrọ aforijin pe oun jẹ ipe naa lati lọ ṣepade pẹlu igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo. Ninu ọrọ aforijin rẹ to fi sita fawọn ọmọ Naijiria, o ṣalaye pe oun ko fẹ kọkọ gba lati lọ fun ipade naa ṣugbọn oun tun daa ro pe yoo fun oun lanfani lati sọ ero rẹ lori awọn ọrọ to n gbona janjan ni Naijiria. Taaooma ṣe eyi lẹyin ti ibẹwo rẹ ọhun bẹrẹ si ni fa ariwo lori ayelujara ti awọn eeyan n gbaa bi ẹni n gba igba ọti. Bi awọn ọmọ Naijiria mii ṣe n kan sara si awọn to lọ fun ipade naa ni awọn mii n tabuku wọn ti wọn si n gboriyin fun apanilẹrin Mr Macaroni to kọ lati lọ ni tirẹ to si ṣalaye. Wọn ni lilọ wọn jẹ lati ṣe igbelarugẹ fun iṣẹ wọn ti wọn yan laayo ni kii ṣe lati sọrọ lorukọ awọn ọdọ Naijiria gẹgẹ bi wọn ṣe jẹ ki awọn eeyan gbagbọ. Kii ṣe awọn Naijiria nikan lo fesi amọ awọn adẹrinpoṣonu naa ti ọrọ kan gaan ti sọ ero ọkan wọn nipa rẹ. Ọkan lara awọn gbajugbaja ajafẹtọ ọmọniyan, Aisha Yesufu sọ fun Taaooma pe ko tilẹ nilo lati tọrọ aforijin lọwọ ẹnikẹni tori pe oniruuru ọna leyan le gba ṣe amuṣẹ nkan. Bẹ naa ni mọ Naijiria kan Mankwat Nisa fesi pe "mo lero pe ẹ ko lọ ṣoju emi nibẹ, to ba ri bẹẹ, ko kan mi". Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi Alùlùgbayì ọmọ Nàìjíríà tó fI Ìlù kojú ìdẹ́yẹsí ní Amẹ́ríkà rèé Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ oo! Ìyá ju ọmọ rẹ̀ méjì sí Kànga Ẹwẹ, bi awọn wọnyii ṣe ni ki wọn ka ọrọ awọn eeyan to n bu wọn si yinyin agbado sẹyin igba, awọn ọmọ Naijria mii ni iṣẹ ara wọn ni wọn ba lọ. Gbajugbaja apanilẹrin ti ko ba wọn pe nibi ipade naa, Debo Adebayo ti ọpọ mọ si Mr Macaroni ni tirẹ ṣalaye idi ti ko fi lọ to si ni oun ko ni ki awọn to lọ ma lọ. Ninu ọrọ to fi sita, o ni idi ti oun ko fi lọ ni pe inu oun ko dun si awọn adari oṣelu oun ko si f ni nkan ṣe pẹlu wọn. O ni o dara bi awọn to ku ba gbagbọ pe biba ijọba joko sọrọ yoo mu ayipada ba awọn nkankan, "ki ẹnikẹni ma si gbe ọbẹ si wọn lọrun pe wọn lọ". Lara awn adẹrinpoṣonu mii to lọ fun ipade naa ni Ayo Ajewole ti ọpọ mọ si Woli Agba. Adeoye Adeyemi Elesho to jẹ ọmọ agba oṣere, Elesho to ni gbogbo igba ti awọn ba n ṣe ifẹhonuhan, oun ti maa n woye ọjọ kan ti oun yoo lanfani lati sọrọ fun awọn adari ijọba lojukoroju. Lara awọn to lọ ni Taooma; Josh Alfred (Josh2funny); Ayo Ajewole (Woli Agba); Adebamiro Adeyanju (Mr Hyenana) ati Adeoye Adeyemi Elesho (Yemi Elesho). | Mr Macaroni, Taaooma, Woli Agba, Adeyemi Elesho sọrọ lórí ìpè láti ṣèpàdé pẹ̀lú ìgbákéjì ààrẹ Yemi Osinbajo Awọn gbajugbaja apanilẹrin bii Debo Mr Macaroni, Taaooma, Woli Agba Ayo Ajewole ati Adeyemi Elesho to jẹ ọmọ agba oṣere, Elesho ti fi ọrọ sita lori ipade kan ti wọn pe wọn si pẹlu igbakeji aar Naijiria, Yemi Osinbajo eyi to di ariwo lori ayelujara lẹnu awọn ọdọ Naijiria. Maryam Apaokagi ti ọpọ mọ si Taaooma ti sọrọ pe oun tọrọ aforijin pe oun jẹ ipe naa lati lọ ṣepade pẹlu igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo. Ninu ọrọ aforijin rẹ to fi sita fawọn ọmọ Naijiria, o ṣalaye pe oun ko fẹ kọkọ gba lati lọ fun ipade naa ṣugbọn oun tun daa ro pe yoo fun oun lanfani lati sọ ero rẹ lori awọn ọrọ to n gbona janjan ni Naijiria. Taaooma ṣe eyi lẹyin ti ibẹwo rẹ ọhun bẹrẹ si ni fa ariwo lori ayelujara ti awọn eeyan n gbaa bi ẹni n gba igba ọti. Bi awọn ọmọ Naijiria mii ṣe n kan sara si awọn to lọ fun ipade naa ni awọn mii n tabuku wọn ti wọn si n gboriyin fun apanilẹrin Mr Macaroni to kọ lati lọ ni tirẹ to si ṣalaye. Wọn ni lilọ wọn jẹ lati ṣe igbelarugẹ fun iṣẹ wọn ti wọn yan laayo ni kii ṣe lati sọrọ lorukọ awọn ọdọ Naijiria gẹgẹ bi wọn ṣe jẹ ki awọn eeyan gbagbọ. Kii ṣe awọn Naijiria nikan lo fesi amọ awọn adẹrinpoṣonu naa ti ọrọ kan gaan ti sọ ero ọkan wọn nipa rẹ. Ọkan lara awọn gbajugbaja ajafẹtọ ọmọniyan, Aisha Yesufu sọ fun Taaooma pe ko tilẹ nilo lati tọrọ aforijin lọwọ ẹnikẹni tori pe oniruuru ọna leyan le gba ṣe amuṣẹ nkan. Bẹ naa ni mọ Naijiria kan Mankwat Nisa fesi pe "mo lero pe ẹ ko lọ ṣoju emi nibẹ, to ba ri bẹẹ, ko kan mi". Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi Alùlùgbayì ọmọ Nàìjíríà tó fI Ìlù kojú ìdẹ́yẹsí ní Amẹ́ríkà rèé Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ oo! Ìyá ju ọmọ rẹ̀ méjì sí Kànga Ẹwẹ, bi awọn wọnyii ṣe ni ki wọn ka ọrọ awọn eeyan to n bu wọn si yinyin agbado sẹyin igba, awọn ọmọ Naijria mii ni iṣẹ ara wọn ni wọn ba lọ. Gbajugbaja apanilẹrin ti ko ba wọn pe nibi ipade naa, Debo Adebayo ti ọpọ mọ si Mr Macaroni ni tirẹ ṣalaye idi ti ko fi lọ to si ni oun ko ni ki awọn to lọ ma lọ. Ninu ọrọ to fi sita, o ni idi ti oun ko fi lọ ni pe inu oun ko dun si awọn adari oṣelu oun ko si f ni nkan ṣe pẹlu wọn. O ni o dara bi awọn to ku ba gbagbọ pe biba ijọba joko sọrọ yoo mu ayipada ba awọn nkankan, "ki ẹnikẹni ma si gbe ọbẹ si wọn lọrun pe wọn lọ". Lara awn adẹrinpoṣonu mii to lọ fun ipade naa ni Ayo Ajewole ti ọpọ mọ si Woli Agba. Adeoye Adeyemi Elesho to jẹ ọmọ agba oṣere, Elesho to ni gbogbo igba ti awọn ba n ṣe ifẹhonuhan, oun ti maa n woye ọjọ kan ti oun yoo lanfani lati sọrọ fun awọn adari ijọba lojukoroju. Lara awọn to lọ ni Taooma; Josh Alfred (Josh2funny); Ayo Ajewole (Woli Agba); Adebamiro Adeyanju (Mr Hyenana) ati Adeoye Adeyemi Elesho (Yemi Elesho). | https://www.bbc.com/yoruba/59196312 |
4religion
| Mbaka missing: Father Ejike Mbaka ti ṣí aṣọ lójú àwọn tó sọ ọ́ dàwátì | Gbajumọ oluṣọaguntan ijọ aguda nipinlẹ Enugu, Ẹniọwọ Ejike Mbaka ti ọpọ mọ si Fada Mbaka ti ṣalaye awọn to wa nidi bo ṣe di awati fun ọjọ meji. Nigba to n ba awọn olujọsin ijọ rẹ sọrọ nileejọsin Adoration ministries ni Umuchigbo Nike nilu Enugu, Fada Mbaka ṣalaye pe awọn alaṣẹ daosisi ijọ Aguda nilu Enugu lo wa nidi bi oun ṣe dawati. O ni Bisọbu agba ijọ aguda nibẹ lo pe oun sibi ipade kan, ibẹ si ni wọn ti fi oun si abẹ ahamọ. O ni ara ẹsun ti wọn ka si oun lẹsẹ̀ ni pe oun gbadura fun Nnamdi Kanu, aṣiwaju ẹgbẹ agbesunmọmi IPOB. Gẹgẹ bi o ṣe sọ fawọn ọmọ ijọ rẹ, ọgbọn ọjọ ni wọn gbero lati fi fi oun si ahamọ ki o to di pe awọn ọmọ ijọ rẹ pariwo sita ti wọn fi tu oun silẹ. Fada Mbaka ṣalaye pe oun ti wọn sọ fun oun ni pe oun yoo wa lahamọ fun oṣu kan fun oun lati gbadura ki oun si ṣe aṣaro lori iṣe oun. O ni oun rọ wọn lati fun oun laaye lati ba awọn eeyan ijọ oun sọrọ ki oun si ti ilẹkun ileejọsin naa "ṣugbọn wọn ni rara, ẹ gbami laaye lati ṣe isin oni fun awọn olujọsin ijọ mi, mi o tilẹ ni sọ fun wọn pe mo wa labẹ ibawi, wọn ni rara. Maa kan sọ fawọn ọmọ ijọ mi ni pe mo n lọ fun adura ọlọgbọn ọjọ, a o pada wa gbogbo wa yoo si bọwọ fun gbogbo nnkan ti wọn ba sọ, wọn ni rara" O ni oun tilẹ bẹ wọn pe ki wọn gbe iranṣẹ Ọlọrun miran lọ si ijọ naa, sibẹ wọn kọ ni. Ni Ọjọru ni okiki kan nigba tawọn ọmọ ijọ Adoration ministries ti Fada Mbaka n ṣe oluṣọaguntan fun wọde nilu Enugu ti wọn si n pariwo pe ki wọn ba awọn wa Fada Mbaka ti wọn ji gbe. Ninu ọrọ rẹ, Fada Mbaka ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ agbofinro DSS kọ lo gbe oun gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe ro. Wọn ti ri ojiṣẹ Ọlọrun, Fr Ejike Mbaka. Ṣaaju ni iroyin jade pe alufaa naa to ni ijọ Adoration Ministry nilu Enugu ti di awati fun bi ọjọ meji. Iṣẹlẹ yii n waye lẹyin ọjọ diẹ ti Mbaka pe ki Aarẹ Muhammadu Buhari fi ipo silẹ nitori bi eto aabo ṣe ri ni Naijiria. Bi iroyin ṣe jade pe wọn ko ri Mbaka, ni awọn alatilẹyin rẹ ti tu jade fun iwọde lọ si ile Olori alufaa ijọ Aguda nilu Enugu. Botilẹ jẹ pe a ko ti i le sọ nkankan nipa bi alufaa naa ṣe pada si ilu tabi ibi to ti n bọ, tilu-tifọn, tijo tayọ ni awọn eeyan fi pade rẹ. Awọn to wa ni ayika alufaa naa sọ pe o ti le ni ọjọ meji ti awọn ti ri Mbaka gbẹyin. A gbọ pe o dagbere fun to sunmọ pe pun n lọ si ile Alufaa Agba ijọ Katoliliiki ni ẹkun Enugu, ṣugbọn wọn ko ri i lati igba naa. Fr Mbaka kọ ẹ̀yìn sí Buhari nítorí kò rí nǹkan jẹ lábẹ́ rẹ̀ - Iléeṣẹ́ Ààrẹ Fr Mbaka, ọmọ ìjọ rẹ̀ kọ̀lu akọ̀ròyìn BBC, wọ́n lù wọ́n ní àlùdojúbolẹ̀ Lasiko ti BBC ṣe abẹwo si inu ọgba ijọ rẹ, Adoration Ministry, niṣe ni eero pe jọ sibẹ, ti wọn si n beere pe nibo ni Father Mbaka wa. Ṣugbọn, BBC ko ti i le sọ ni pato boya wọn ji alufaa naa gbe lọ ni, boya o farapamọ ni tabi wa ni ọdọ awọn agbofinro. Bakan naa ni awọn alaṣẹ ijọ Aguda nilu Enugu sọ pe awọn ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa. Alufaa kan to sunmọ Mbaka naa sọ pe oun ko gbọ nipa didi awati rẹ, ṣugbọn ko gbe ipe oun si ori ẹrọ ibanisọrọ rẹ. Iṣẹlẹ yii si ti mu ki awọn ọmọ ijọ rẹ bẹrẹ iwọde. | Mbaka missing: Father Ejike Mbaka ti ṣí aṣọ lójú àwọn tó sọ ọ́ dàwátì Gbajumọ oluṣọaguntan ijọ aguda nipinlẹ Enugu, Ẹniọwọ Ejike Mbaka ti ọpọ mọ si Fada Mbaka ti ṣalaye awọn to wa nidi bo ṣe di awati fun ọjọ meji. Nigba to n ba awọn olujọsin ijọ rẹ sọrọ nileejọsin Adoration ministries ni Umuchigbo Nike nilu Enugu, Fada Mbaka ṣalaye pe awọn alaṣẹ daosisi ijọ Aguda nilu Enugu lo wa nidi bi oun ṣe dawati. O ni Bisọbu agba ijọ aguda nibẹ lo pe oun sibi ipade kan, ibẹ si ni wọn ti fi oun si abẹ ahamọ. O ni ara ẹsun ti wọn ka si oun lẹsẹ̀ ni pe oun gbadura fun Nnamdi Kanu, aṣiwaju ẹgbẹ agbesunmọmi IPOB. Gẹgẹ bi o ṣe sọ fawọn ọmọ ijọ rẹ, ọgbọn ọjọ ni wọn gbero lati fi fi oun si ahamọ ki o to di pe awọn ọmọ ijọ rẹ pariwo sita ti wọn fi tu oun silẹ. Fada Mbaka ṣalaye pe oun ti wọn sọ fun oun ni pe oun yoo wa lahamọ fun oṣu kan fun oun lati gbadura ki oun si ṣe aṣaro lori iṣe oun. O ni oun rọ wọn lati fun oun laaye lati ba awọn eeyan ijọ oun sọrọ ki oun si ti ilẹkun ileejọsin naa "ṣugbọn wọn ni rara, ẹ gbami laaye lati ṣe isin oni fun awọn olujọsin ijọ mi, mi o tilẹ ni sọ fun wọn pe mo wa labẹ ibawi, wọn ni rara. Maa kan sọ fawọn ọmọ ijọ mi ni pe mo n lọ fun adura ọlọgbọn ọjọ, a o pada wa gbogbo wa yoo si bọwọ fun gbogbo nnkan ti wọn ba sọ, wọn ni rara" O ni oun tilẹ bẹ wọn pe ki wọn gbe iranṣẹ Ọlọrun miran lọ si ijọ naa, sibẹ wọn kọ ni. Ni Ọjọru ni okiki kan nigba tawọn ọmọ ijọ Adoration ministries ti Fada Mbaka n ṣe oluṣọaguntan fun wọde nilu Enugu ti wọn si n pariwo pe ki wọn ba awọn wa Fada Mbaka ti wọn ji gbe. Ninu ọrọ rẹ, Fada Mbaka ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ agbofinro DSS kọ lo gbe oun gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe ro. Wọn ti ri ojiṣẹ Ọlọrun, Fr Ejike Mbaka. Ṣaaju ni iroyin jade pe alufaa naa to ni ijọ Adoration Ministry nilu Enugu ti di awati fun bi ọjọ meji. Iṣẹlẹ yii n waye lẹyin ọjọ diẹ ti Mbaka pe ki Aarẹ Muhammadu Buhari fi ipo silẹ nitori bi eto aabo ṣe ri ni Naijiria. Bi iroyin ṣe jade pe wọn ko ri Mbaka, ni awọn alatilẹyin rẹ ti tu jade fun iwọde lọ si ile Olori alufaa ijọ Aguda nilu Enugu. Botilẹ jẹ pe a ko ti i le sọ nkankan nipa bi alufaa naa ṣe pada si ilu tabi ibi to ti n bọ, tilu-tifọn, tijo tayọ ni awọn eeyan fi pade rẹ. Awọn to wa ni ayika alufaa naa sọ pe o ti le ni ọjọ meji ti awọn ti ri Mbaka gbẹyin. A gbọ pe o dagbere fun to sunmọ pe pun n lọ si ile Alufaa Agba ijọ Katoliliiki ni ẹkun Enugu, ṣugbọn wọn ko ri i lati igba naa. Fr Mbaka kọ ẹ̀yìn sí Buhari nítorí kò rí nǹkan jẹ lábẹ́ rẹ̀ - Iléeṣẹ́ Ààrẹ Fr Mbaka, ọmọ ìjọ rẹ̀ kọ̀lu akọ̀ròyìn BBC, wọ́n lù wọ́n ní àlùdojúbolẹ̀ Lasiko ti BBC ṣe abẹwo si inu ọgba ijọ rẹ, Adoration Ministry, niṣe ni eero pe jọ sibẹ, ti wọn si n beere pe nibo ni Father Mbaka wa. Ṣugbọn, BBC ko ti i le sọ ni pato boya wọn ji alufaa naa gbe lọ ni, boya o farapamọ ni tabi wa ni ọdọ awọn agbofinro. Bakan naa ni awọn alaṣẹ ijọ Aguda nilu Enugu sọ pe awọn ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa. Alufaa kan to sunmọ Mbaka naa sọ pe oun ko gbọ nipa didi awati rẹ, ṣugbọn ko gbe ipe oun si ori ẹrọ ibanisọrọ rẹ. Iṣẹlẹ yii si ti mu ki awọn ọmọ ijọ rẹ bẹrẹ iwọde. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-56998652 |
4religion
| Ondo kidnap: Fowokemi Ogedengbe, ọmọ Pasitọ Deeper Life tí wọ́n jígbé l'Ondo ní àwọn ajínigbé kò tíì pe àwọn | Awọn ẹbi ati ara Pasitọ ijọ Deeper Life ti wọn jigbe lọ ni ilu Akure, Otamayomi Ogedengbe ni awọn ko i tii gbọ ohun kankan lati ọdọ awọn janduku to ji i gbe lọ. Iroyin to lo ori ayelujara ni pe awọn ajinigbe ọhun beere fun ọgbọn miliọnu naira lalẹ Ọjọru nigba ti wọn pe ẹbi pasitọ naa. Iroyin mii tiẹ sọ pe awọn janduku ajinigbe pawo naa sọ pe owo itusilẹ naa ko gbọdọ din ni ọgbọn miliọnu. Ṣugbọn ọmọbinrin pasitọ naa, Fowokemi Ogedengbe sọ fun BBC Yoruba pe irọ funfun balau ni iroyin tawọn kan n gbe kiri. Fowokemi ṣalaye pe ẹbi pasitọ Deeper Life ọhun ko ti gbọ lati ọdọ awọn ajinigbe titi di akoko yii. Ọmọ baba naa ni: ''A ko mọ ibi ti awọn to kọ iroyin pe wọn ti tu u silẹ ti gbó iroyin naa. Bi emi ṣe rii ka lori ayelujara niyẹn, amọ ko si otitọ kan ninu iroyin naa. A ko mọ ibi ti baba mi wa bayii nitori awọn ajinigbe naa ko tii pe wa,'' Fowokemi lo ṣalaye bẹẹ. O rọ awọn eeyan lati maa fi adura ran idile awọn lọwọ wi pe ki awọn janduku ajinigbe naa le fi olori ile wọn silẹ. Ọmọbinrin Pasitọ Ogedengbe, Fowokẹmi ni inu ipaya ati ibẹru ni awọn wa nitori awọn ajinigbe naa ko tii kan si wọn. O ni baba oun ni ilera to si ni awọn oogun ti oun lo ni ojoojumọ, amọ lati igba ti wọn ti jigbe lọ yii awọn ko gbọ nkankan. Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Karun un ni wọn ji pasitọ Godwin Mayomi Ogedengbe lẹyin to pari isin ninu ile ijọsin rẹ ni nkan bi aago mẹsan an alẹ. | Ondo kidnap: Fowokemi Ogedengbe, ọmọ Pasitọ Deeper Life tí wọ́n jígbé l'Ondo ní àwọn ajínigbé kò tíì pe àwọn Awọn ẹbi ati ara Pasitọ ijọ Deeper Life ti wọn jigbe lọ ni ilu Akure, Otamayomi Ogedengbe ni awọn ko i tii gbọ ohun kankan lati ọdọ awọn janduku to ji i gbe lọ. Iroyin to lo ori ayelujara ni pe awọn ajinigbe ọhun beere fun ọgbọn miliọnu naira lalẹ Ọjọru nigba ti wọn pe ẹbi pasitọ naa. Iroyin mii tiẹ sọ pe awọn janduku ajinigbe pawo naa sọ pe owo itusilẹ naa ko gbọdọ din ni ọgbọn miliọnu. Ṣugbọn ọmọbinrin pasitọ naa, Fowokemi Ogedengbe sọ fun BBC Yoruba pe irọ funfun balau ni iroyin tawọn kan n gbe kiri. Fowokemi ṣalaye pe ẹbi pasitọ Deeper Life ọhun ko ti gbọ lati ọdọ awọn ajinigbe titi di akoko yii. Ọmọ baba naa ni: ''A ko mọ ibi ti awọn to kọ iroyin pe wọn ti tu u silẹ ti gbó iroyin naa. Bi emi ṣe rii ka lori ayelujara niyẹn, amọ ko si otitọ kan ninu iroyin naa. A ko mọ ibi ti baba mi wa bayii nitori awọn ajinigbe naa ko tii pe wa,'' Fowokemi lo ṣalaye bẹẹ. O rọ awọn eeyan lati maa fi adura ran idile awọn lọwọ wi pe ki awọn janduku ajinigbe naa le fi olori ile wọn silẹ. Ọmọbinrin Pasitọ Ogedengbe, Fowokẹmi ni inu ipaya ati ibẹru ni awọn wa nitori awọn ajinigbe naa ko tii kan si wọn. O ni baba oun ni ilera to si ni awọn oogun ti oun lo ni ojoojumọ, amọ lati igba ti wọn ti jigbe lọ yii awọn ko gbọ nkankan. Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Karun un ni wọn ji pasitọ Godwin Mayomi Ogedengbe lẹyin to pari isin ninu ile ijọsin rẹ ni nkan bi aago mẹsan an alẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57104205 |
2health
| "Mo ní àìsàn Lupus, n kò le bá ọkọ mi lòpọ̀ fún ọdún márùn-ún àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìgbeyàwó" | Adura gbogbo ẹda ni pe ka ma se aisan amọ nigba to ba de adura ki ọlọjọ mase de lo ku ta maa gba. Obinrin kan ree, ti a ko fẹ darukọ tabi fi oju rẹ han to ni aisan to maa n mu ki awọn eroja ara maa ba ara wọn ja, eyi ti wọn n pe ni Lupus. Bẹẹ ba gbagbe, gbajumọ osere kan, Kemi Afolabi Adedipe naa kede losu diẹ sẹyin pe oun ni aisan naa, eyi to n ba agọ ara oun ja. Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ lori aisan naa, obinrin alaisan ọhun ati dokita kan to ni imọ nipa arun ọhun, Hakeem Olaosebikan salaye itu ti aisan naa le fi ẹni to ba mu pa. Ninu alaye obinrin naa, o sọ pe ọdun ti oun se igbeyawo gan ni aisan Lupus yii bẹrẹ, bii iba ati ikọ wiwu si lo ba wọle. O ni oun ko tiẹ tete mọ lara afi igba ti ikọ naa le laleju, ti ayẹwo si fi fidi rẹ mulẹ lẹyin ọdun meji ti oun ti n jẹ irora pe aisan Lupus lo n ba oun finra. O salaye pe oun ko tiẹ kọkọ gbagbọ, ti oun si morile oke okun, ki wn wa sọ pe lootọ ni Lupus wa ni agọ ara oun. Ninu ọrọ rẹ, obinrin alaisan Lupus naa ni orisirisi ẹya ara ni Lupus maa n kọju ija si nitori o le ba oju ati awọ ara jẹ. Amọ o ni niti oun, ẹdọ fooro oun lo kọkọ nawọ gan, ti oun yoo si wukọ awule tọntọ, ti awọ ara oun gan ko si bọ lọwọ rẹ. O fikun pe aisan naa ni irora pupọ to si dabi ki oun lọ pokunso lati bọ lọwọ rẹ, ti oun si nilo lati fi isẹ oojọ oun silẹ nitori aisan naa. Arabinrin naa ni ọpẹlọpẹ adura ni oun fi bimọ kan soso ti oun bi nitori pe aisan Lupus maa n jo oyun mu ni. Idi si ree, to fi ni awọn dokita gba oun ati ọkọ oun nimọran lati mase sun mọ ara awọn, titi di ẹyin ọdun marun. Asiko naa si ni oun bi ọmọ kan soso ti oun bi naa pẹlu ẹbẹadura ati atilẹyin ọkọ oun, to si n mọ riri awn obi ati ọkọ rẹ fun atilyin wọn. Arabinrin naa gba gba awọn to ni aisan naa nimọran pe Lupus see wo amọ ko le san patapata ninu agọ ara ni, ti wn si nilo ifẹ ati iranwọ ẹbi wn lati gbe ile aye. Nigba to n ba wa sọrọ, dokita Olaosebikan to nimọ nipa arun Lupus salaye pe obinrin ni arun naa maa n ba finra julọ ju awọn ọkunrin lọ. Dokita ni awọn mọge ti wọn wa ni ọjọ ori ọdun mejidinlogun siwaju si lo saba maa n ni arun Lupus julọ. O salaye pe lara awọn ohun ta fi le mọ Lupus ni ara gbigbona, keeyan maa laagun pupọ ati ikọ hihu. O wa gba awọn ẹbi awọn to ba ni arun naa nimọran lati sugba wọn nitori wn nilo ifẹ ati iranwọ lati ọdọ ẹbi wọn. | "Mo ní àìsàn Lupus, n kò le bá ọkọ mi lòpọ̀ fún ọdún márùn-ún àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìgbeyàwó" Adura gbogbo ẹda ni pe ka ma se aisan amọ nigba to ba de adura ki ọlọjọ mase de lo ku ta maa gba. Obinrin kan ree, ti a ko fẹ darukọ tabi fi oju rẹ han to ni aisan to maa n mu ki awọn eroja ara maa ba ara wọn ja, eyi ti wọn n pe ni Lupus. Bẹẹ ba gbagbe, gbajumọ osere kan, Kemi Afolabi Adedipe naa kede losu diẹ sẹyin pe oun ni aisan naa, eyi to n ba agọ ara oun ja. Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ lori aisan naa, obinrin alaisan ọhun ati dokita kan to ni imọ nipa arun ọhun, Hakeem Olaosebikan salaye itu ti aisan naa le fi ẹni to ba mu pa. Ninu alaye obinrin naa, o sọ pe ọdun ti oun se igbeyawo gan ni aisan Lupus yii bẹrẹ, bii iba ati ikọ wiwu si lo ba wọle. O ni oun ko tiẹ tete mọ lara afi igba ti ikọ naa le laleju, ti ayẹwo si fi fidi rẹ mulẹ lẹyin ọdun meji ti oun ti n jẹ irora pe aisan Lupus lo n ba oun finra. O salaye pe oun ko tiẹ kọkọ gbagbọ, ti oun si morile oke okun, ki wn wa sọ pe lootọ ni Lupus wa ni agọ ara oun. Ninu ọrọ rẹ, obinrin alaisan Lupus naa ni orisirisi ẹya ara ni Lupus maa n kọju ija si nitori o le ba oju ati awọ ara jẹ. Amọ o ni niti oun, ẹdọ fooro oun lo kọkọ nawọ gan, ti oun yoo si wukọ awule tọntọ, ti awọ ara oun gan ko si bọ lọwọ rẹ. O fikun pe aisan naa ni irora pupọ to si dabi ki oun lọ pokunso lati bọ lọwọ rẹ, ti oun si nilo lati fi isẹ oojọ oun silẹ nitori aisan naa. Arabinrin naa ni ọpẹlọpẹ adura ni oun fi bimọ kan soso ti oun bi nitori pe aisan Lupus maa n jo oyun mu ni. Idi si ree, to fi ni awọn dokita gba oun ati ọkọ oun nimọran lati mase sun mọ ara awọn, titi di ẹyin ọdun marun. Asiko naa si ni oun bi ọmọ kan soso ti oun bi naa pẹlu ẹbẹadura ati atilẹyin ọkọ oun, to si n mọ riri awn obi ati ọkọ rẹ fun atilyin wọn. Arabinrin naa gba gba awọn to ni aisan naa nimọran pe Lupus see wo amọ ko le san patapata ninu agọ ara ni, ti wn si nilo ifẹ ati iranwọ ẹbi wn lati gbe ile aye. Nigba to n ba wa sọrọ, dokita Olaosebikan to nimọ nipa arun Lupus salaye pe obinrin ni arun naa maa n ba finra julọ ju awọn ọkunrin lọ. Dokita ni awọn mọge ti wọn wa ni ọjọ ori ọdun mejidinlogun siwaju si lo saba maa n ni arun Lupus julọ. O salaye pe lara awọn ohun ta fi le mọ Lupus ni ara gbigbona, keeyan maa laagun pupọ ati ikọ hihu. O wa gba awọn ẹbi awọn to ba ni arun naa nimọran lati sugba wọn nitori wn nilo ifẹ ati iranwọ lati ọdọ ẹbi wọn. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cv2nqj9xnwyo |
2health
| Coronavirus in Nigeria: Ṣé lóòtọ́ọ́ ni pé ìtọ̀ àti imí màálù le wo ààrùn coronavirus? | Oriṣiiriṣii nnkan lawọn eeyan n sọ pe o le wo aarun coronavirus ti o ba gbogbo aye finra lọwọ. Ọkan lara wọn ni itọ ati igbẹ maalu. Ṣugbọn ohun ti a mọ ni pe itọ tabi igbẹ maalu ko le ṣ'oogun aarun covid-19. Gẹgẹ bi ọrọ ti ajọ to n ri si eto ilera lagbaye, WHO ṣe sọ, itọ ati igbẹ maalu ko le sọ bo ya eeyan ni aarun coronavirus. Ẹ wo alaye lẹkunrẹrẹ ninu fidio yii. | Coronavirus in Nigeria: Ṣé lóòtọ́ọ́ ni pé ìtọ̀ àti imí màálù le wo ààrùn coronavirus? Oriṣiiriṣii nnkan lawọn eeyan n sọ pe o le wo aarun coronavirus ti o ba gbogbo aye finra lọwọ. Ọkan lara wọn ni itọ ati igbẹ maalu. Ṣugbọn ohun ti a mọ ni pe itọ tabi igbẹ maalu ko le ṣ'oogun aarun covid-19. Gẹgẹ bi ọrọ ti ajọ to n ri si eto ilera lagbaye, WHO ṣe sọ, itọ ati igbẹ maalu ko le sọ bo ya eeyan ni aarun coronavirus. Ẹ wo alaye lẹkunrẹrẹ ninu fidio yii. | https://www.bbc.com/yoruba/52385712 |
1entertainment
| Ọkọ Lizzy Anjorin : Abdulateef Lawal ní Ọlọ́rún ló so oun àti Lizzy pọ̀, ẹ̀dá kan kò sì le yà àwọn | Ọkọ gbajugbaja oṣerebinrin Lizzy Anjorin, Alhaji Abdullateef Lawal Adegboyega ti salaye idi to se ni iyawo mẹrin saaju ko to fẹ Lizzy Anjorin. Alhaji Lawal, ninu fidio kan to gba ori ayeluyara kan, wa sekilọ fun awọn iyawo rẹ mẹrin to ku lati ṣọ ara wọn lori ọrọ Lizzy Anjorin. Adegboyega fi ikilọ naa lede lasiko to n sọrọ lori ayelujara nipa ija ati awuyewuye to n waye laarin awọn iyawo akọfẹ rẹ ati Lizzy Anjorin. Ọkan lara awọn iyawo mẹrin naa, Fola, lo kọkọ lọ si ori ẹrọ ayelujara pe Adegboyega ko tọju oun ati awọn ọmọ ohun. Amọ Adegboyega fi aridaju lede pe irọ patapata ni ati owo to fi sọ wọ si Fola, to fi mọ owo ile to n gbe. Bi mo ṣe di oniyawo mẹrin re e: Ramota, iya Ayomide ni iyawo akọkọ mi: Abdulateef Lawal Adegboyega ni Ramota, tii se Iya Ayomide ni oun kọkọ fẹ ni aarọ ọjọ oun amọ awọn dijọ gbe papọ fun igba diẹ. O ni nigba ti ọrọ awọn ko fẹ ye ara awọn, ni awọn yago fun ara awọn, ko maa ba di pe awọn lu ara awọn pa sinu ile. O ni lati igba ti awọn ti fi ara awọn silẹ, oun n tọju rẹ, ti oun si n se awọn ẹtọ ti o yẹ ki oun se, koda akọbi rẹ gan ti wa nile ẹkọ giga bayii. "Mo dupẹ lori iyawo mi keji, mo si gbadura fun pe Ọlọrun yoo ba mi saanu rẹ ni gbogbo ibi to wa, ti yoo si gbe alaanu dide fun. Mo ri pe obinrin alalubarika to fẹ jere ọmọ dọjọ alẹ ni, ti n ko si fẹ sọrọ ju bayii lọ lori ọrọ iyawo mi keji yii." ko mọ ju ko lọ si ibi ayẹyẹ ni ọṣọọṣẹ. Monsurat, iya Amuda ni iyawo mi kẹta amọ ale yiyan pọ fun: Alhaji Lawal ni Monsura ni iyawo oun kẹta, ti oun si fẹ nilana ẹsin Islam amọ oun se iyawo alarede pẹlu rẹ amọ o ni o n hu awọn iwa kan ni oun se pa ti. O salaye pe igba mẹta ọtọọtọ ni oun ti ka ọkunrin mọ ọdọ rẹ. Akọkọ ni igba ti oun rinrin ajo amọ ti oun de lẹyin ọjọ kẹfa, ti oun si ba ọkunrin ninu yara pẹlu rẹ. "Mo ba Alfa lọdọ rẹ to wọ asọ mi sọrun, ti iyawo mi si ni o wa se alua pẹlu oun ni lati ọjọ mẹfa sẹyin, mo yari amọ wọn bẹ mi, ti mo si gba. Ko tun pẹ mo tun ka ni igba keji pẹluọ́kunrin apọn kan to n gbe oke ile wa, ti wọn jọ joko sinu yara wa, ti iywao mi si wọ asọ oorun to fi ihooho ara rẹ silẹ, wọn bẹ mi, mo tun gbọ. Ni igba kẹta, mo tun ka iyawo mi pẹlu ale, ọkunrin yii, mo mọ daadaa, ti iyawo mi si maa n ran mi si pe awọn dijọ n dajọ papọ ni, ase ale rẹ ni. Wahala Monsura ni Alhaji Lawal sọ pe o ti oun sita, ti obinrin naa si tun maa n ya asọ mọ oun lọrun tawn ba ti n ja. Iyawo lọ pe ọlọ pa si mi, mo ni maa fi ile silẹ fun, ko kan jẹ ki n ko asọ mi, mo si lọ n ya ile gbe lọdọ ọrẹ mi kan, ibẹ si ni mo ti pade Fola. Lọwọ bayii, Monsura ti wa nile ọkọ miran, to si tun wa n pada maa da ile ru pẹlu Lizzy, irọ si lo n pa pe oun mọ Lizzy ri. Fola ni iyawo mi kẹrin, amọ kii se ẹni ti eeyan n ba to: Alhaji Lawal ni Fola, tii se iyawo kẹrin ni akọkọ, o si yẹ ki araye bi leere pe ki lo pa ọkọ rẹ akọkọ ati idi ti awn ẹbi ọkọ naa ko se fẹ ri loju. Fola yii kii se ẹni ti eeyan n ba to rara, amọ asiko ti wahala wa laarin emi ati Monsura ni mo pade Fola yii, ta si n fẹ ara wa. "Fola ko sọ fun mi nibẹrẹ pe oun ti bimọ ri, ẹnu awọn ọrẹ mi ni mo ti gbọ pe o ti bimọ meji, ti oun naa si sọ pe lootọ ni nigba ti mo bi i. O salaye gbogbo itan aye rẹ fun mi, ipo tawọn obi rẹ wa ati oun gan, ti wọn n lo yara kan soso ni Agege amọ ẹsẹ rẹ kii duro soju kan. Nigba to ya lo ni oun ti loyun fun mi, ara fu mi pe kii se emi ni mo ni oyun amọ mo ni to ba bimọ, a se ayẹwo DNA lati mọ baba to ni ọmọ, ti mo si gba ile fun si adugbo Fagba." Lawal ni oun ba Fola gbe pọ fun osu kan amọ oun ko le ba gbe papọ ni oun se lọ gba ile si Ikorodu. O ni Fola yii ko mọ̀ ju ariya ọsọọsẹ lọ, ko m isẹ se, to si maa n fi owo ile ẹkọ ọmọ ra asọ ariya. ''Mi o ṣe iyawo pẹlu Fola nitori gbogbo awọn ọmọ to wa ni ọwọ rẹ mẹtẹẹta, o da mi loju pe ẹmi kọ ni mo ni awọn ọmọ naa. Lẹyin naa ni mo sọ wi pe ka lọ ṣe ayẹwọ ẹjẹ boya emi ni mo ni awọn ọmọ naa, amọ Fola kọ pe ka ṣe DNA. Nigba to ya lo ni oun ni oyun keji fun mi, ti mo si yari pe oyun naa kii se temi, ti ọmọ mi si sọ fun mi pe ọrẹ mi maa n wa sun ti Fola mọju." ''Irọ ni gbogbo ohun ti awọn iyawo mi n sọ fun awọn ọmọ Naijiria lori ẹrọ ayelujara pe Lizzy gba ọkọ awọn'' Ọkọ gbajugbaja oṣerebinrin Lizzy Anjorin, Abdullateef Lawal Adegboyega ni Lizzy Anjọrin nikan ni oun ṣe iyawo oloruka pẹlu, amọ oun ṣe Nikkah pẹlu iyawo oun meji, Iya Ayomide ati Monsuratu. Ọkọ gbajugbaja oṣerebinrin Lizzy Anjorin, Abdullateef Lawal Adegboyega ti ni irọ ni pe Lizzy Anjọrin gba ọkọ awọn iyawo oun mẹta to ba nilẹ. Abdullateef Lawal Adegboyega ni oun ti wa lai si iyawo ni ile fun ọdun meji ko to di pe oun fẹ Lizzy Anjorin. Bakan naa lo sapejuwe Anjorin gẹgẹ bi obinrin oni inu ire to fẹran awọn eniyan amọ ko gba ibajẹ eniyan. O rọ awọn ọmọ Naijiria lati ma a ṣe iwadii awọn iroyin ti wọn ba n ri lori ẹrọ ayelujara nitori awọn eniyan kan fẹ ba oun lorukọ jẹ ni. Adegboyega wa kilọ fun awọn iyawo mẹta to ku wi pe ti wọn ko ba ṣọra wọn, wọn yoo rugi oyin lori ọrọ kubakugbe ti wọn n sọ kaakiri nipa Lizzy Anjorin. | Ọkọ Lizzy Anjorin : Abdulateef Lawal ní Ọlọ́rún ló so oun àti Lizzy pọ̀, ẹ̀dá kan kò sì le yà àwọn Ọkọ gbajugbaja oṣerebinrin Lizzy Anjorin, Alhaji Abdullateef Lawal Adegboyega ti salaye idi to se ni iyawo mẹrin saaju ko to fẹ Lizzy Anjorin. Alhaji Lawal, ninu fidio kan to gba ori ayeluyara kan, wa sekilọ fun awọn iyawo rẹ mẹrin to ku lati ṣọ ara wọn lori ọrọ Lizzy Anjorin. Adegboyega fi ikilọ naa lede lasiko to n sọrọ lori ayelujara nipa ija ati awuyewuye to n waye laarin awọn iyawo akọfẹ rẹ ati Lizzy Anjorin. Ọkan lara awọn iyawo mẹrin naa, Fola, lo kọkọ lọ si ori ẹrọ ayelujara pe Adegboyega ko tọju oun ati awọn ọmọ ohun. Amọ Adegboyega fi aridaju lede pe irọ patapata ni ati owo to fi sọ wọ si Fola, to fi mọ owo ile to n gbe. Bi mo ṣe di oniyawo mẹrin re e: Ramota, iya Ayomide ni iyawo akọkọ mi: Abdulateef Lawal Adegboyega ni Ramota, tii se Iya Ayomide ni oun kọkọ fẹ ni aarọ ọjọ oun amọ awọn dijọ gbe papọ fun igba diẹ. O ni nigba ti ọrọ awọn ko fẹ ye ara awọn, ni awọn yago fun ara awọn, ko maa ba di pe awọn lu ara awọn pa sinu ile. O ni lati igba ti awọn ti fi ara awọn silẹ, oun n tọju rẹ, ti oun si n se awọn ẹtọ ti o yẹ ki oun se, koda akọbi rẹ gan ti wa nile ẹkọ giga bayii. "Mo dupẹ lori iyawo mi keji, mo si gbadura fun pe Ọlọrun yoo ba mi saanu rẹ ni gbogbo ibi to wa, ti yoo si gbe alaanu dide fun. Mo ri pe obinrin alalubarika to fẹ jere ọmọ dọjọ alẹ ni, ti n ko si fẹ sọrọ ju bayii lọ lori ọrọ iyawo mi keji yii." ko mọ ju ko lọ si ibi ayẹyẹ ni ọṣọọṣẹ. Monsurat, iya Amuda ni iyawo mi kẹta amọ ale yiyan pọ fun: Alhaji Lawal ni Monsura ni iyawo oun kẹta, ti oun si fẹ nilana ẹsin Islam amọ oun se iyawo alarede pẹlu rẹ amọ o ni o n hu awọn iwa kan ni oun se pa ti. O salaye pe igba mẹta ọtọọtọ ni oun ti ka ọkunrin mọ ọdọ rẹ. Akọkọ ni igba ti oun rinrin ajo amọ ti oun de lẹyin ọjọ kẹfa, ti oun si ba ọkunrin ninu yara pẹlu rẹ. "Mo ba Alfa lọdọ rẹ to wọ asọ mi sọrun, ti iyawo mi si ni o wa se alua pẹlu oun ni lati ọjọ mẹfa sẹyin, mo yari amọ wọn bẹ mi, ti mo si gba. Ko tun pẹ mo tun ka ni igba keji pẹluọ́kunrin apọn kan to n gbe oke ile wa, ti wọn jọ joko sinu yara wa, ti iywao mi si wọ asọ oorun to fi ihooho ara rẹ silẹ, wọn bẹ mi, mo tun gbọ. Ni igba kẹta, mo tun ka iyawo mi pẹlu ale, ọkunrin yii, mo mọ daadaa, ti iyawo mi si maa n ran mi si pe awọn dijọ n dajọ papọ ni, ase ale rẹ ni. Wahala Monsura ni Alhaji Lawal sọ pe o ti oun sita, ti obinrin naa si tun maa n ya asọ mọ oun lọrun tawn ba ti n ja. Iyawo lọ pe ọlọ pa si mi, mo ni maa fi ile silẹ fun, ko kan jẹ ki n ko asọ mi, mo si lọ n ya ile gbe lọdọ ọrẹ mi kan, ibẹ si ni mo ti pade Fola. Lọwọ bayii, Monsura ti wa nile ọkọ miran, to si tun wa n pada maa da ile ru pẹlu Lizzy, irọ si lo n pa pe oun mọ Lizzy ri. Fola ni iyawo mi kẹrin, amọ kii se ẹni ti eeyan n ba to: Alhaji Lawal ni Fola, tii se iyawo kẹrin ni akọkọ, o si yẹ ki araye bi leere pe ki lo pa ọkọ rẹ akọkọ ati idi ti awn ẹbi ọkọ naa ko se fẹ ri loju. Fola yii kii se ẹni ti eeyan n ba to rara, amọ asiko ti wahala wa laarin emi ati Monsura ni mo pade Fola yii, ta si n fẹ ara wa. "Fola ko sọ fun mi nibẹrẹ pe oun ti bimọ ri, ẹnu awọn ọrẹ mi ni mo ti gbọ pe o ti bimọ meji, ti oun naa si sọ pe lootọ ni nigba ti mo bi i. O salaye gbogbo itan aye rẹ fun mi, ipo tawọn obi rẹ wa ati oun gan, ti wọn n lo yara kan soso ni Agege amọ ẹsẹ rẹ kii duro soju kan. Nigba to ya lo ni oun ti loyun fun mi, ara fu mi pe kii se emi ni mo ni oyun amọ mo ni to ba bimọ, a se ayẹwo DNA lati mọ baba to ni ọmọ, ti mo si gba ile fun si adugbo Fagba." Lawal ni oun ba Fola gbe pọ fun osu kan amọ oun ko le ba gbe papọ ni oun se lọ gba ile si Ikorodu. O ni Fola yii ko mọ̀ ju ariya ọsọọsẹ lọ, ko m isẹ se, to si maa n fi owo ile ẹkọ ọmọ ra asọ ariya. ''Mi o ṣe iyawo pẹlu Fola nitori gbogbo awọn ọmọ to wa ni ọwọ rẹ mẹtẹẹta, o da mi loju pe ẹmi kọ ni mo ni awọn ọmọ naa. Lẹyin naa ni mo sọ wi pe ka lọ ṣe ayẹwọ ẹjẹ boya emi ni mo ni awọn ọmọ naa, amọ Fola kọ pe ka ṣe DNA. Nigba to ya lo ni oun ni oyun keji fun mi, ti mo si yari pe oyun naa kii se temi, ti ọmọ mi si sọ fun mi pe ọrẹ mi maa n wa sun ti Fola mọju." ''Irọ ni gbogbo ohun ti awọn iyawo mi n sọ fun awọn ọmọ Naijiria lori ẹrọ ayelujara pe Lizzy gba ọkọ awọn'' Ọkọ gbajugbaja oṣerebinrin Lizzy Anjorin, Abdullateef Lawal Adegboyega ni Lizzy Anjọrin nikan ni oun ṣe iyawo oloruka pẹlu, amọ oun ṣe Nikkah pẹlu iyawo oun meji, Iya Ayomide ati Monsuratu. Ọkọ gbajugbaja oṣerebinrin Lizzy Anjorin, Abdullateef Lawal Adegboyega ti ni irọ ni pe Lizzy Anjọrin gba ọkọ awọn iyawo oun mẹta to ba nilẹ. Abdullateef Lawal Adegboyega ni oun ti wa lai si iyawo ni ile fun ọdun meji ko to di pe oun fẹ Lizzy Anjorin. Bakan naa lo sapejuwe Anjorin gẹgẹ bi obinrin oni inu ire to fẹran awọn eniyan amọ ko gba ibajẹ eniyan. O rọ awọn ọmọ Naijiria lati ma a ṣe iwadii awọn iroyin ti wọn ba n ri lori ẹrọ ayelujara nitori awọn eniyan kan fẹ ba oun lorukọ jẹ ni. Adegboyega wa kilọ fun awọn iyawo mẹta to ku wi pe ti wọn ko ba ṣọra wọn, wọn yoo rugi oyin lori ọrọ kubakugbe ti wọn n sọ kaakiri nipa Lizzy Anjorin. | https://www.bbc.com/yoruba/media-58621787 |
4religion
| Ìjọba ti ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti n ta 'omi ayẹta ìbọn' fun àwọn olùjọ́sìn ní Kogi | Ijọba ipinlẹ Kogi ti ti ile ijọsin kan pa fun ẹsun pe alufaa ijọ naa n ta omi ayẹta fun awọn ọmọ ijọ. Ọjọ Aje ni wọn gbe ilẹkun ile ijọsin naa, New Jerusalem Deliverance Ministry lẹyin ti Gomina Yahaya Bello paṣẹ rẹ Pasitọ ijọ naa, Peter Adeiza tun ṣi ileewosan lai gba aṣẹ lọwọ ijọba lati ọdun 2008. Igbagbọ wa pe ọpọ eeyan lo ti padanu ẹmi wọn nitori ilana ti wọn n gba ṣe itọju wọn. Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle jabọ pe, yatọ si pe wọn n ṣe itọju aisan, ati igbẹbi alaboyun nibẹ, wọn tun n lo ṣọọṣi naa fun itọju aarun ọpọlọ, ti wọn si so ọpọ wọn pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ. Ijọba sọ pe Alufaa Adeiza n lu awọn ọmọ ijọ rẹ ni jibiti nipa ti ta omi kan fun wọn, ‘ti ko ni i jẹ ki ọta ibọn ko ran wọn’. Awọn ọmọ ijọ naa kan sọ fun awọn akọroyin pe lootọ ni baba wọn ninu Oluwa ọhun n fun awọn ni iwosan lori oriṣiriṣi aisan ati aarun. Oludamọran lori aabo fun ijọba ipinlẹ Kogi, Jerry Omodara, sọ pe awọn ọlọpaa ati DSS ti kọkọ mu pasitọ naa nigba kan, lati tọpinpin nkan to n ṣẹlẹ ninu ṣọọṣi naa. Omodara sọ pe awọn ni ẹri to to lati fihan nile ẹjọ pe iṣeṣi pasitọ naa tako ilana ẹsin ati iṣegun oyinbo. O ṣalaye pe laipẹ ni wọn o gbe e lọ sile ẹjọ. | Ìjọba ti ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti n ta 'omi ayẹta ìbọn' fun àwọn olùjọ́sìn ní Kogi Ijọba ipinlẹ Kogi ti ti ile ijọsin kan pa fun ẹsun pe alufaa ijọ naa n ta omi ayẹta fun awọn ọmọ ijọ. Ọjọ Aje ni wọn gbe ilẹkun ile ijọsin naa, New Jerusalem Deliverance Ministry lẹyin ti Gomina Yahaya Bello paṣẹ rẹ Pasitọ ijọ naa, Peter Adeiza tun ṣi ileewosan lai gba aṣẹ lọwọ ijọba lati ọdun 2008. Igbagbọ wa pe ọpọ eeyan lo ti padanu ẹmi wọn nitori ilana ti wọn n gba ṣe itọju wọn. Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle jabọ pe, yatọ si pe wọn n ṣe itọju aisan, ati igbẹbi alaboyun nibẹ, wọn tun n lo ṣọọṣi naa fun itọju aarun ọpọlọ, ti wọn si so ọpọ wọn pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ. Ijọba sọ pe Alufaa Adeiza n lu awọn ọmọ ijọ rẹ ni jibiti nipa ti ta omi kan fun wọn, ‘ti ko ni i jẹ ki ọta ibọn ko ran wọn’. Awọn ọmọ ijọ naa kan sọ fun awọn akọroyin pe lootọ ni baba wọn ninu Oluwa ọhun n fun awọn ni iwosan lori oriṣiriṣi aisan ati aarun. Oludamọran lori aabo fun ijọba ipinlẹ Kogi, Jerry Omodara, sọ pe awọn ọlọpaa ati DSS ti kọkọ mu pasitọ naa nigba kan, lati tọpinpin nkan to n ṣẹlẹ ninu ṣọọṣi naa. Omodara sọ pe awọn ni ẹri to to lati fihan nile ẹjọ pe iṣeṣi pasitọ naa tako ilana ẹsin ati iṣegun oyinbo. O ṣalaye pe laipẹ ni wọn o gbe e lọ sile ẹjọ. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/czvnzpvy9jzo |
4religion
| COZA: Lẹ́yìn ìwadìí PFN ni CAN tó leè sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Fatoyinbo | Apapọ ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN, ti sọ pe oun ko mọ nkankan nipa bi awọn kan ṣe ṣe abẹwo a n bẹ lẹyin rẹ si COZA. Lọjọ Aiku to kọja ni awọn alufaa naa ṣe abẹwo ọhun si ijọ Commonwealth of Zion Assembly. Ninu atẹjade kan ti Oludari Apapọ fun eto ofin ati ikede fun CAN, Ajihinrere Kwamkur Samuel Vondip fi sita lọjọ Aje lo ti ni ọrọ ko ri bẹẹ. O ni ẹgbẹ CAN sọ pe oun ko lọwọ si abẹwo ọhun ati fidio rẹ to gba ori ayelujara. Bakan naa ni Kwankur sọ pe awọn pasitọ to wa ninu fidio naa lọ sile ijọsin COZA latinu ifẹ ọkan wọn ni. ''Eyi ni lati sọ fun gbogbo eniyan pe wọn ti pe akiyesi Aarẹ ẹgbẹ CAN, Ẹni Ọwọ Samson O.A Ayokunle si iroyin ati fidio kan lori ayelujara pe ẹgbẹ CAN ran awọn aṣoju lọ sinu ijọ pe awọn ṣatilẹyin fun Pasitọ Agba ijọ naa, Biodun Fatoyinbo, ti wọn fi ẹsun ifipabanilopọ kan." O ni "Atẹjade yii wa lati jẹ ki gbogbo awọn olori ẹsin Kristiẹni, araalu, ati awọn to fẹran otitọ, mọ pe ẹgbẹ CAN tabi Aarẹ CAN ko fi ọwọ si tabi mọ nkankan nipa abẹwo atilẹyin naa." Ẹgbẹ CAN sọ pe oun ko ti i yi ohun pada lori ọrọ ti oun sọ tẹlẹ pe lootọ ni awọn ko faramọ iwa ibajẹ kankan lati ibikibi, ṣugbọn oun ti fi aaye silẹ fun ẹgbẹ Ijọ Ẹmi Mimọ, PFN ti ijọ COZA n ṣe, lati ṣewadi ẹsun ifipabanilopọ naa, ko si jabọ fun ẹgbẹ CAN. '' A le fi idi rẹ mulẹ pe ẹgbẹ PFN ti bẹrẹ iwadii, abọ iwadii na yoo si jade sita titi ọsẹ meji si asiko yii. A ko si ni ṣe idiwọ fun ijiya to ba tọ si ẹnikẹni to ba hu iwqa ti ko tọ ọ. Aarẹ ẹgbẹ CAN, Ẹni Ọwọ Samson O.A Ayokunle, sọ fun BBC Yoruba pe ẹgbẹ CAN ko le ṣe atilẹyin fun Fatotinbo tabi Busola lai jẹ pe ẹgbẹ PFN ti CAN fun ni aṣẹ lati ṣe iwadii ọrọ naa ba jabọ. " A gbọdọ tẹle ilana to yẹ, ao si ri i pe a tẹle nitori ki otitọ le jọba.'' Ọjọ Aiku ni fidio kan gba ori ayelujara, to si ṣafihan awọn pasitọ kan ti wọn ni awọn jẹ aṣoju ẹgbẹ CAN ẹka ilu Abuja, lẹnu abẹwo lọ si olu ijọ COZA, to wa nilu Abuja. Nibẹ ni wọn ti sọ fun Pasitọ Biodun fatoyinbo pe digbi ni awọn wa lẹyin rẹ lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an. Fidio naa mu ki ọpọlọpọ ọmọ Naijiria o koro oju si ẹgbẹ CAN. Oṣu Kẹfa ni iyawo gbaju-gbaja akọrin, Timi Dakolo, Busola Dakolo, ninu ifọrọwanilẹnuwo kan fi ẹsun kan Fatoyinbo pe o fi ipa ba oun lo pọ lẹẹmeji ọtọọtọ ki oun to o pe ẹni ogun ọdun. Ẹsun naa fa awuyewuye l'oriṣiriṣi jakejado orilẹede Naijiria. Awọn kan tilẹ ṣe iwọde lọ si ẹka ileejọsin COZA nilu Abuja ati Eko, pe ki Biodun Fatoyinbo kuro ni ipo Pasitọ ninu ijọ naa. Lẹyin eyi ni Fatoyinbo kede pe oun ti yẹba naa. Ṣaaju lo ti fesi si ẹsun ti Dakolo fi kan an pe oun ko fi ipa ba ẹnikẹni lo pọ ri. | COZA: Lẹ́yìn ìwadìí PFN ni CAN tó leè sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Fatoyinbo Apapọ ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN, ti sọ pe oun ko mọ nkankan nipa bi awọn kan ṣe ṣe abẹwo a n bẹ lẹyin rẹ si COZA. Lọjọ Aiku to kọja ni awọn alufaa naa ṣe abẹwo ọhun si ijọ Commonwealth of Zion Assembly. Ninu atẹjade kan ti Oludari Apapọ fun eto ofin ati ikede fun CAN, Ajihinrere Kwamkur Samuel Vondip fi sita lọjọ Aje lo ti ni ọrọ ko ri bẹẹ. O ni ẹgbẹ CAN sọ pe oun ko lọwọ si abẹwo ọhun ati fidio rẹ to gba ori ayelujara. Bakan naa ni Kwankur sọ pe awọn pasitọ to wa ninu fidio naa lọ sile ijọsin COZA latinu ifẹ ọkan wọn ni. ''Eyi ni lati sọ fun gbogbo eniyan pe wọn ti pe akiyesi Aarẹ ẹgbẹ CAN, Ẹni Ọwọ Samson O.A Ayokunle si iroyin ati fidio kan lori ayelujara pe ẹgbẹ CAN ran awọn aṣoju lọ sinu ijọ pe awọn ṣatilẹyin fun Pasitọ Agba ijọ naa, Biodun Fatoyinbo, ti wọn fi ẹsun ifipabanilopọ kan." O ni "Atẹjade yii wa lati jẹ ki gbogbo awọn olori ẹsin Kristiẹni, araalu, ati awọn to fẹran otitọ, mọ pe ẹgbẹ CAN tabi Aarẹ CAN ko fi ọwọ si tabi mọ nkankan nipa abẹwo atilẹyin naa." Ẹgbẹ CAN sọ pe oun ko ti i yi ohun pada lori ọrọ ti oun sọ tẹlẹ pe lootọ ni awọn ko faramọ iwa ibajẹ kankan lati ibikibi, ṣugbọn oun ti fi aaye silẹ fun ẹgbẹ Ijọ Ẹmi Mimọ, PFN ti ijọ COZA n ṣe, lati ṣewadi ẹsun ifipabanilopọ naa, ko si jabọ fun ẹgbẹ CAN. '' A le fi idi rẹ mulẹ pe ẹgbẹ PFN ti bẹrẹ iwadii, abọ iwadii na yoo si jade sita titi ọsẹ meji si asiko yii. A ko si ni ṣe idiwọ fun ijiya to ba tọ si ẹnikẹni to ba hu iwqa ti ko tọ ọ. Aarẹ ẹgbẹ CAN, Ẹni Ọwọ Samson O.A Ayokunle, sọ fun BBC Yoruba pe ẹgbẹ CAN ko le ṣe atilẹyin fun Fatotinbo tabi Busola lai jẹ pe ẹgbẹ PFN ti CAN fun ni aṣẹ lati ṣe iwadii ọrọ naa ba jabọ. " A gbọdọ tẹle ilana to yẹ, ao si ri i pe a tẹle nitori ki otitọ le jọba.'' Ọjọ Aiku ni fidio kan gba ori ayelujara, to si ṣafihan awọn pasitọ kan ti wọn ni awọn jẹ aṣoju ẹgbẹ CAN ẹka ilu Abuja, lẹnu abẹwo lọ si olu ijọ COZA, to wa nilu Abuja. Nibẹ ni wọn ti sọ fun Pasitọ Biodun fatoyinbo pe digbi ni awọn wa lẹyin rẹ lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an. Fidio naa mu ki ọpọlọpọ ọmọ Naijiria o koro oju si ẹgbẹ CAN. Oṣu Kẹfa ni iyawo gbaju-gbaja akọrin, Timi Dakolo, Busola Dakolo, ninu ifọrọwanilẹnuwo kan fi ẹsun kan Fatoyinbo pe o fi ipa ba oun lo pọ lẹẹmeji ọtọọtọ ki oun to o pe ẹni ogun ọdun. Ẹsun naa fa awuyewuye l'oriṣiriṣi jakejado orilẹede Naijiria. Awọn kan tilẹ ṣe iwọde lọ si ẹka ileejọsin COZA nilu Abuja ati Eko, pe ki Biodun Fatoyinbo kuro ni ipo Pasitọ ninu ijọ naa. Lẹyin eyi ni Fatoyinbo kede pe oun ti yẹba naa. Ṣaaju lo ti fesi si ẹsun ti Dakolo fi kan an pe oun ko fi ipa ba ẹnikẹni lo pọ ri. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49007306 |
1entertainment
| Mide Funmi-Martins àtí Olamide àbúrò rẹ̀ ti ayé ń bú u lé lórí ti wà papọ̀ | Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọmọ ìyá kìí yà, ọmọ baba ní ń báni dalẹ́. Nínú oṣù kejì, ọdún 2021 ní àwọn ènìyàn lórí ẹ̀rọ ayélujára Instagram yọ sùtì ètè sí gbajúgbajà òṣèré Mide Martins nítorí tí ìròyìn kan pé ó pa àbúrò rẹ̀ tí ìyá rẹ̀, Funmi Martins bí fún Shina Peters kó tó kú tì. Àwọn ènìyàn lásìkò náà bú Mide Martins pé pẹ̀lú bí Ọlọ́run ṣe kẹ́ ẹ tó kò lè mú àbúrò rẹ̀, Damilare sọ́dọ̀ rẹ̀. Ẹ ó rántí pé Damilare fi síta lọ́dún náà lọ́hùn ún pé òun kò ṣetán láti gbé ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n òun tí kò bèrè òun fún ọdún mọ́kàndínlógún. Ó ti tó ọdún mẹ́fà, méje tí mo ti rí Àùntí Mide Funmi Martins gbẹ̀yìn, wọ́n tún ṣẹ̀ ń ṣèlérí - Damilare Mo ń ṣe ẹ̀tọ́ mi fún Damilare lọ́dọ̀ màmá àgbà, àmọ́ ǹkan tí ẹ kò mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí ló pọ̀ - Mide-Funmi Martins Kí ni ìtumọ̀ pé Mide Funmi Martins kò sí níbi tí Damilare àti Shina Peters ti parí ìjà? ESABOD gbé ìjà Mide Martins rù sórí ara rẹ̀ ó ń fi èpè ránṣẹ́ sí Adunni Olorisa àtàwọn míì Mide Martins fèsì sọ́rọ̀ Ashabi Olorisha tó ní kò tún ibojì màmá rẹ̀ ṣe tàbí tọ́jú àbúrò rẹ̀ Èyí mú kí Mide Martins náà jáde síta lásìkò náà wí pé òun kò mọ̀-ọ́n-mọ̀ pa Damilare ti nítorí pé ẹ̀jẹ̀ òun ni. Mide Martins ní Damilare ni kò fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ òun. Ẹ̀wẹ̀, ọdún kan lẹ́yìn rẹ̀, Mide Martins fi àwòrán kan sórí ẹ̀rọ Instagram lónìí léyìí tó ń ṣàfihàn pé Damilare ti wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Mide Martins ẹgbọn rẹ si wa nibi ayẹyẹ naa. Ko si aridaju boya Mide Martins kọ pé mọ̀lẹ́bí ṣaájú ohunkóhun tí òun àti Damilare sì dì mọ́ ara wọn. Kòdá èyí tí ń mú kí àwọn ènìyàn máa gbóríyìn fún un fún ipa tó kó nínú ìgbésí ayé ọmọ náà. | Mide Funmi-Martins àtí Olamide àbúrò rẹ̀ ti ayé ń bú u lé lórí ti wà papọ̀ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọmọ ìyá kìí yà, ọmọ baba ní ń báni dalẹ́. Nínú oṣù kejì, ọdún 2021 ní àwọn ènìyàn lórí ẹ̀rọ ayélujára Instagram yọ sùtì ètè sí gbajúgbajà òṣèré Mide Martins nítorí tí ìròyìn kan pé ó pa àbúrò rẹ̀ tí ìyá rẹ̀, Funmi Martins bí fún Shina Peters kó tó kú tì. Àwọn ènìyàn lásìkò náà bú Mide Martins pé pẹ̀lú bí Ọlọ́run ṣe kẹ́ ẹ tó kò lè mú àbúrò rẹ̀, Damilare sọ́dọ̀ rẹ̀. Ẹ ó rántí pé Damilare fi síta lọ́dún náà lọ́hùn ún pé òun kò ṣetán láti gbé ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n òun tí kò bèrè òun fún ọdún mọ́kàndínlógún. Ó ti tó ọdún mẹ́fà, méje tí mo ti rí Àùntí Mide Funmi Martins gbẹ̀yìn, wọ́n tún ṣẹ̀ ń ṣèlérí - Damilare Mo ń ṣe ẹ̀tọ́ mi fún Damilare lọ́dọ̀ màmá àgbà, àmọ́ ǹkan tí ẹ kò mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí ló pọ̀ - Mide-Funmi Martins Kí ni ìtumọ̀ pé Mide Funmi Martins kò sí níbi tí Damilare àti Shina Peters ti parí ìjà? ESABOD gbé ìjà Mide Martins rù sórí ara rẹ̀ ó ń fi èpè ránṣẹ́ sí Adunni Olorisa àtàwọn míì Mide Martins fèsì sọ́rọ̀ Ashabi Olorisha tó ní kò tún ibojì màmá rẹ̀ ṣe tàbí tọ́jú àbúrò rẹ̀ Èyí mú kí Mide Martins náà jáde síta lásìkò náà wí pé òun kò mọ̀-ọ́n-mọ̀ pa Damilare ti nítorí pé ẹ̀jẹ̀ òun ni. Mide Martins ní Damilare ni kò fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ òun. Ẹ̀wẹ̀, ọdún kan lẹ́yìn rẹ̀, Mide Martins fi àwòrán kan sórí ẹ̀rọ Instagram lónìí léyìí tó ń ṣàfihàn pé Damilare ti wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Mide Martins ẹgbọn rẹ si wa nibi ayẹyẹ naa. Ko si aridaju boya Mide Martins kọ pé mọ̀lẹ́bí ṣaájú ohunkóhun tí òun àti Damilare sì dì mọ́ ara wọn. Kòdá èyí tí ń mú kí àwọn ènìyàn máa gbóríyìn fún un fún ipa tó kó nínú ìgbésí ayé ọmọ náà. | https://www.bbc.com/yoruba/60501036 |
4religion
| Hijab Ban in India: Ilé ẹjọ́ Karnakata ní kò sí ibi kankan nínú Kùránì tó ti pọ́n ní dandan fún obìnrin láti lo Hijab | Ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Karnataka, orílẹ̀ èdè India ti gbé ìdájọ́ kan kalẹ̀ wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò ní ẹ̀tọ́ láti máa lo hìjáàbù ní àwọn ìyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́. Ilé ẹjọ́ náà ní hìjáàbù lílò kò pọn dandan nínú ẹ̀sìn Islam àti pé kò ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀. Àwọn adájọ́ mẹ́ta tó gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ ní gbígba àwọn obìnrin mùsùlumí láàyè láti máa wọ hìjáàbù nínú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ yóò jẹ́ ìtàpá sí òfin orílẹ̀ èdè náà. Nínú àgbékalẹ̀ ìwé alábala mọ́kàndínláàdóje tó kún fún àwọn ọ̀rọ̀ láti inú Kùránì, àwọn adájọ́ náà ní kò sí ibi tí ẹ̀sìn Islam ti pá ní dandan fún àwọn obìnrin, láti máa wọ hìjáàbù àti pé tí òfin kò bá pa á ni dandan kò yẹ kí orílẹ̀ èdè náà mu ni tipátipá. Ìdájọ́ yìí ló ń ṣe àtìlẹyìn fún àṣẹ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Karnataka ti pa ṣaájú wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò ní ẹ̀tọ́ láti máa wọ hìjáàbù nínú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́. Ilé ẹjọ́ ní ìjọba ní àṣẹ láti sọ irúfẹ́ aṣọ tó bá fẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa wọ̀. Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn? Ní oṣù kìíní ọdún yìí ni ilé ẹ̀kọ́ kan ní ìpínlẹ̀ Karnataka fòfin de gbígba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin láti máa wọ hìjáàbù ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́. Ìpinu yìí ló fà á tí àwọn mùsùlùmí ní ìpínlẹ̀ náà ṣe ìwọ́de tó sì fi di ọ̀rọ̀ ńlá. Ní ọ̀pọ̀ ọjọ́ ní ìjọba fi ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan lórí pa nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Lẹ́yìn èyí ni àwọn obìnrin náà gba ilé ẹjọ́ láti pe ìjọba lẹ́jọ́ pé ìwé òfin orílẹ̀ èdè India fi àyè gba àwọn láti lo hìjáàbù níbiníbi àti ní ìgbàkúgbà. A ó pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn: Ọ̀jọ̀gbọ́n Ravi Varma Kumar tó jẹ́ agbẹjọ́rò àgbà fún àwọn olùpejọ́ ní àwọn yóò ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ. Bákan náà ní àwọn olùpẹjọ́ ní ilé ẹjọ́ já àwọn kulẹ̀ fún ìdí àwọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú ilé ẹjọ́ náà mọ́. Wọ́n ní àwọn yóò ja ìjà náà títí dé òpin. Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ náà ń lọ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mùsùlùmí kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́, kódà ọ̀pọ̀ wọn ni kò ṣe ìdánwò nítorí hìjáàbù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin náà fi àyè sílẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti wọ hìjáàbù nígbà tí wọ́n bá wà ní ọgbà ilé ẹ̀kọ́, wọ́n ní kò tẹ́ àwọn lọ́rùn láti máa gèlè àwọn bá fẹ́ wọ kílàsì. Ẹ̀wẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ náà ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà tẹ́ àwọn lọ́rùn. | Hijab Ban in India: Ilé ẹjọ́ Karnakata ní kò sí ibi kankan nínú Kùránì tó ti pọ́n ní dandan fún obìnrin láti lo Hijab Ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Karnataka, orílẹ̀ èdè India ti gbé ìdájọ́ kan kalẹ̀ wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò ní ẹ̀tọ́ láti máa lo hìjáàbù ní àwọn ìyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́. Ilé ẹjọ́ náà ní hìjáàbù lílò kò pọn dandan nínú ẹ̀sìn Islam àti pé kò ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀. Àwọn adájọ́ mẹ́ta tó gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ ní gbígba àwọn obìnrin mùsùlumí láàyè láti máa wọ hìjáàbù nínú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ yóò jẹ́ ìtàpá sí òfin orílẹ̀ èdè náà. Nínú àgbékalẹ̀ ìwé alábala mọ́kàndínláàdóje tó kún fún àwọn ọ̀rọ̀ láti inú Kùránì, àwọn adájọ́ náà ní kò sí ibi tí ẹ̀sìn Islam ti pá ní dandan fún àwọn obìnrin, láti máa wọ hìjáàbù àti pé tí òfin kò bá pa á ni dandan kò yẹ kí orílẹ̀ èdè náà mu ni tipátipá. Ìdájọ́ yìí ló ń ṣe àtìlẹyìn fún àṣẹ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Karnataka ti pa ṣaájú wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò ní ẹ̀tọ́ láti máa wọ hìjáàbù nínú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́. Ilé ẹjọ́ ní ìjọba ní àṣẹ láti sọ irúfẹ́ aṣọ tó bá fẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa wọ̀. Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn? Ní oṣù kìíní ọdún yìí ni ilé ẹ̀kọ́ kan ní ìpínlẹ̀ Karnataka fòfin de gbígba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin láti máa wọ hìjáàbù ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́. Ìpinu yìí ló fà á tí àwọn mùsùlùmí ní ìpínlẹ̀ náà ṣe ìwọ́de tó sì fi di ọ̀rọ̀ ńlá. Ní ọ̀pọ̀ ọjọ́ ní ìjọba fi ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan lórí pa nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Lẹ́yìn èyí ni àwọn obìnrin náà gba ilé ẹjọ́ láti pe ìjọba lẹ́jọ́ pé ìwé òfin orílẹ̀ èdè India fi àyè gba àwọn láti lo hìjáàbù níbiníbi àti ní ìgbàkúgbà. A ó pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn: Ọ̀jọ̀gbọ́n Ravi Varma Kumar tó jẹ́ agbẹjọ́rò àgbà fún àwọn olùpejọ́ ní àwọn yóò ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ. Bákan náà ní àwọn olùpẹjọ́ ní ilé ẹjọ́ já àwọn kulẹ̀ fún ìdí àwọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú ilé ẹjọ́ náà mọ́. Wọ́n ní àwọn yóò ja ìjà náà títí dé òpin. Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ náà ń lọ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mùsùlùmí kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́, kódà ọ̀pọ̀ wọn ni kò ṣe ìdánwò nítorí hìjáàbù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin náà fi àyè sílẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti wọ hìjáàbù nígbà tí wọ́n bá wà ní ọgbà ilé ẹ̀kọ́, wọ́n ní kò tẹ́ àwọn lọ́rùn láti máa gèlè àwọn bá fẹ́ wọ kílàsì. Ẹ̀wẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ náà ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà tẹ́ àwọn lọ́rùn. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60754940 |
5sports
| Manchester United vs Tottenham: Man United ré Mourinho àti Tottenham lẹ́pa lórí pápá Old Trafford | Papa iṣere Old Trafford yeruku lala lẹyin ti Tottenham ati manchester United tutọ sira wọn loju ninu ifẹsẹwọnsẹ Premier League to waye lalẹ Ọjọru. Manchester United rii wi pe ipadabọ wa Jose Mourinho si papa iṣere Old Trafford, iya lo ba de. Lẹyin iṣẹju mẹfa ti ere bọọlu ọhun bẹrẹ ni Marcus Rashford gbayo alakọkọ sawọn fun Manchester United eleyi to mu Man U wa niwaju. Man U gbiyanju lati gbayo keji wọle, amọ Deli Alli sọ ere bọọlu ọhun di ọmi alayo kọkọkan. Ẹlẹsẹ ayo Rashford tun fakọyọ kete ti wọn bẹrẹ ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa lẹyin to gba pẹnariti wọle Tottenham eleyi to mu ki Man U pada maa siwaju. Ológìnní t'àjò dé...Mourinho padà sí Manchester United lónìí! Oni lonii jẹ ẹni a bẹ lọwẹ. Lalẹ Ọjọru ni gbajugbaja akọnimọọgba Jose Mourinho yoo pada si papa iṣere ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United nibi to ti ṣiṣẹ ki wọn to fọwọ oṣi juwe ile fun un lọdun 2018. Amọ ikọ agbabọọlu Tottenham ni Mourinho n ko o lọ koju Man United lọtẹ yii lẹyin to gbaṣẹ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu naa ni kopẹ kopẹ yii. Ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham ti jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn gba ninu idije Premier League lati igba ti Mourinho ti rọ pe Mauricio Pochettino gẹgẹ bi akọnimọọgba Spurs. Koda ipo Tottenham ti gberu si lori tabili idije Premier League, ipo kẹfa ni wọn wa bayii lẹyin ti wọn fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn gba sẹyin. Awọn agbabọọlu Tottenham gan an ti mọ pe igba ọtun ti de, agbabọọlu bi Dele Alli ti ina ere bọọlu rẹ ti n jo ajo rẹyin tẹlẹ ti sọji bayii. Ipo kẹfa ni Man U wa ki wọn to da Mourinho duro lẹnu iṣẹ, ṣugbọn ipo kẹwaa ni wọn wa bayii labẹ aṣẹ akọnimọọgba tuntun, Ole Gunnar Solskjaer. Ọmi alayo meji meji ni Manchester United ta pẹlu Aston Villa ninu ere bọọlu ti wọn gba kẹyin lọjọ Aiku. | Manchester United vs Tottenham: Man United ré Mourinho àti Tottenham lẹ́pa lórí pápá Old Trafford Papa iṣere Old Trafford yeruku lala lẹyin ti Tottenham ati manchester United tutọ sira wọn loju ninu ifẹsẹwọnsẹ Premier League to waye lalẹ Ọjọru. Manchester United rii wi pe ipadabọ wa Jose Mourinho si papa iṣere Old Trafford, iya lo ba de. Lẹyin iṣẹju mẹfa ti ere bọọlu ọhun bẹrẹ ni Marcus Rashford gbayo alakọkọ sawọn fun Manchester United eleyi to mu Man U wa niwaju. Man U gbiyanju lati gbayo keji wọle, amọ Deli Alli sọ ere bọọlu ọhun di ọmi alayo kọkọkan. Ẹlẹsẹ ayo Rashford tun fakọyọ kete ti wọn bẹrẹ ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa lẹyin to gba pẹnariti wọle Tottenham eleyi to mu ki Man U pada maa siwaju. Ológìnní t'àjò dé...Mourinho padà sí Manchester United lónìí! Oni lonii jẹ ẹni a bẹ lọwẹ. Lalẹ Ọjọru ni gbajugbaja akọnimọọgba Jose Mourinho yoo pada si papa iṣere ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United nibi to ti ṣiṣẹ ki wọn to fọwọ oṣi juwe ile fun un lọdun 2018. Amọ ikọ agbabọọlu Tottenham ni Mourinho n ko o lọ koju Man United lọtẹ yii lẹyin to gbaṣẹ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu naa ni kopẹ kopẹ yii. Ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham ti jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn gba ninu idije Premier League lati igba ti Mourinho ti rọ pe Mauricio Pochettino gẹgẹ bi akọnimọọgba Spurs. Koda ipo Tottenham ti gberu si lori tabili idije Premier League, ipo kẹfa ni wọn wa bayii lẹyin ti wọn fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn gba sẹyin. Awọn agbabọọlu Tottenham gan an ti mọ pe igba ọtun ti de, agbabọọlu bi Dele Alli ti ina ere bọọlu rẹ ti n jo ajo rẹyin tẹlẹ ti sọji bayii. Ipo kẹfa ni Man U wa ki wọn to da Mourinho duro lẹnu iṣẹ, ṣugbọn ipo kẹwaa ni wọn wa bayii labẹ aṣẹ akọnimọọgba tuntun, Ole Gunnar Solskjaer. Ọmi alayo meji meji ni Manchester United ta pẹlu Aston Villa ninu ere bọọlu ti wọn gba kẹyin lọjọ Aiku. | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-50663728 |
3politics
| Wọ́n ti fi orúkọ mi ráńṣẹ́ sí INEC gẹ́gẹ́ bí igbákejì Peter Obi – Doyin Okupe | Adarí ìpolongo ètò ìdìbò fún olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Doyin Okupe ti kéde wí pé òun ni ẹni tí ẹgbẹ́ òṣèlú náà fà kalẹ̀ báyìí gẹ́gẹ́ bí igbákejì Peter Obi. Okupe ló kéde ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń kópa lórí ètò “Politics today” ti iléeṣẹ́ iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán Channels Television ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2022. Bákan náà ló ní ó ṣeéṣe kí òun fi ipò náà sílẹ̀ tí àwọn bá rí ọ̀dọ́ tó lè gba ipò lọ́wọ́ òun. Ó ní ìgbésẹ̀ tó ṣì ń lọ lọ́wọ́ ni ọ̀rọ̀ yíyan igbákejì Ààrẹ jẹ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party nítorí àwọn ṣì ń bá àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn sọ̀rọ̀ láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn. Ó fi kun pé òfin àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà fi àyè gba pé olùdíje sípò Ààrẹ le fi orúkọ kan sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igbakejì, tó sì lè yí orúkọ náà padà tí àwọn ìpinu tàbí àyípadà mìíràn bá wáyé nínú ẹgbẹ́. “Ohun ta fẹ́ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ni pé kí àwọn ọ̀dọ́ pọ̀ nínú òṣèlú, gbogbo àwa ta sì ti fìgbà kan wà nínú ìjọba nígbà kan rí sẹ́yìn ti ṣetán láti fipò sílẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ tó ń bọ̀ lẹ́yìn wa. “Irú àwọn ìgbésẹ̀ báyìí ló le mú kí àwọn ọ̀dọ́ dé ipò àṣẹ àti olórí, mo ṣetán láti fipò náà sílẹ̀ kí àwọn ọ̀dọ́ le rí ìgbéga. Doyin Okupe ló ti fìgbà kan rí jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì lórí ìròyìn àti ìpolongo sí Olusegun Obasanjo nígbà tó wà nípò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ. Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, ti kede gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa, gẹgẹ bii igbakeji rẹ. Atiku funra rẹ lo kede orukọ Okowa nibi eto kan ti wọn ṣe niluu Abuja, ko to fi ikede naa sita loju opo Twitter rẹ. Nigba to n sọrọ lori eredi to ṣe yan Okowa, Atiku sọ pe ẹni ti yoo ṣe igbakeji oun gbọdọ jẹ ẹni ti yoo le di ipo Aarẹ mu, ti yoo si le ṣe atilẹyin fun oun gẹgẹ bii Aarẹ. O fi kun pe irufẹ ẹni bẹẹ gbọdọ ṣe afihan iṣokan Naijiria ati ẹni ti ko ni bẹru lati sọrọ soke ti nnkan ko ba lọ dede, ti yoo si le fun ijọba ni amọran to dara. Atiku tun sọ pe igbakeji oun gbọdọ ni imọ nipa ibi ti nnkan bajẹ de ni Naijiria ati ọna ti awọn fi le ṣe atunṣe. Ni bayii ti wọn ti kede Okowa gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije gẹgẹ bii igbakeji Atiku, igbimọ kan yoo ṣe ayẹwo ati iwadii ọkunrin naa. Ṣaaju lawọn eeyan kan ti kọkọ n sọ pe gomina Nyesom Wike ni Atiku yoo yan gẹgẹ bii igbakeji rẹ. Amọ lọjọru ni ẹgbẹ oṣelu PDP kede pe ko si ohun to jọ pe awọn yoo yan Wike gẹgẹ bii igbakeji Atiku. Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Debo Ologunagba ni irọ nla gbaa ni awọn iroyin to lọ laarin igboro pe PDP ti yan Wike sipo ẹni ti yoo dije du ipo igabkeji ọhun. Ti ẹ ko ba gbagbe, ibo 237 ni Wike ni ninu eto idibo abẹnu ẹgbẹ ọhun lati yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu eto idibo ọdun to n bọ. Amọ Wike fidi rẹmi, nigba ti Atiku gbegba oroke. Lẹyin eto idibo naa ni Wike ṣo ni gbangba pe ẹnikẹni ti ẹgbẹ ọhun ba ti yan gẹgẹ bii Aarẹ ni oun yoo ṣatilẹyin fun, fun ilọsiwaju ẹgbẹ naa. | Wọ́n ti fi orúkọ mi ráńṣẹ́ sí INEC gẹ́gẹ́ bí igbákejì Peter Obi – Doyin Okupe Adarí ìpolongo ètò ìdìbò fún olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Doyin Okupe ti kéde wí pé òun ni ẹni tí ẹgbẹ́ òṣèlú náà fà kalẹ̀ báyìí gẹ́gẹ́ bí igbákejì Peter Obi. Okupe ló kéde ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń kópa lórí ètò “Politics today” ti iléeṣẹ́ iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán Channels Television ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2022. Bákan náà ló ní ó ṣeéṣe kí òun fi ipò náà sílẹ̀ tí àwọn bá rí ọ̀dọ́ tó lè gba ipò lọ́wọ́ òun. Ó ní ìgbésẹ̀ tó ṣì ń lọ lọ́wọ́ ni ọ̀rọ̀ yíyan igbákejì Ààrẹ jẹ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party nítorí àwọn ṣì ń bá àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn sọ̀rọ̀ láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn. Ó fi kun pé òfin àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà fi àyè gba pé olùdíje sípò Ààrẹ le fi orúkọ kan sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igbakejì, tó sì lè yí orúkọ náà padà tí àwọn ìpinu tàbí àyípadà mìíràn bá wáyé nínú ẹgbẹ́. “Ohun ta fẹ́ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ni pé kí àwọn ọ̀dọ́ pọ̀ nínú òṣèlú, gbogbo àwa ta sì ti fìgbà kan wà nínú ìjọba nígbà kan rí sẹ́yìn ti ṣetán láti fipò sílẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ tó ń bọ̀ lẹ́yìn wa. “Irú àwọn ìgbésẹ̀ báyìí ló le mú kí àwọn ọ̀dọ́ dé ipò àṣẹ àti olórí, mo ṣetán láti fipò náà sílẹ̀ kí àwọn ọ̀dọ́ le rí ìgbéga. Doyin Okupe ló ti fìgbà kan rí jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì lórí ìròyìn àti ìpolongo sí Olusegun Obasanjo nígbà tó wà nípò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ. Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, ti kede gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa, gẹgẹ bii igbakeji rẹ. Atiku funra rẹ lo kede orukọ Okowa nibi eto kan ti wọn ṣe niluu Abuja, ko to fi ikede naa sita loju opo Twitter rẹ. Nigba to n sọrọ lori eredi to ṣe yan Okowa, Atiku sọ pe ẹni ti yoo ṣe igbakeji oun gbọdọ jẹ ẹni ti yoo le di ipo Aarẹ mu, ti yoo si le ṣe atilẹyin fun oun gẹgẹ bii Aarẹ. O fi kun pe irufẹ ẹni bẹẹ gbọdọ ṣe afihan iṣokan Naijiria ati ẹni ti ko ni bẹru lati sọrọ soke ti nnkan ko ba lọ dede, ti yoo si le fun ijọba ni amọran to dara. Atiku tun sọ pe igbakeji oun gbọdọ ni imọ nipa ibi ti nnkan bajẹ de ni Naijiria ati ọna ti awọn fi le ṣe atunṣe. Ni bayii ti wọn ti kede Okowa gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije gẹgẹ bii igbakeji Atiku, igbimọ kan yoo ṣe ayẹwo ati iwadii ọkunrin naa. Ṣaaju lawọn eeyan kan ti kọkọ n sọ pe gomina Nyesom Wike ni Atiku yoo yan gẹgẹ bii igbakeji rẹ. Amọ lọjọru ni ẹgbẹ oṣelu PDP kede pe ko si ohun to jọ pe awọn yoo yan Wike gẹgẹ bii igbakeji Atiku. Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Debo Ologunagba ni irọ nla gbaa ni awọn iroyin to lọ laarin igboro pe PDP ti yan Wike sipo ẹni ti yoo dije du ipo igabkeji ọhun. Ti ẹ ko ba gbagbe, ibo 237 ni Wike ni ninu eto idibo abẹnu ẹgbẹ ọhun lati yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu eto idibo ọdun to n bọ. Amọ Wike fidi rẹmi, nigba ti Atiku gbegba oroke. Lẹyin eto idibo naa ni Wike ṣo ni gbangba pe ẹnikẹni ti ẹgbẹ ọhun ba ti yan gẹgẹ bii Aarẹ ni oun yoo ṣatilẹyin fun, fun ilọsiwaju ẹgbẹ naa. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cg6z5v54d53o |
4religion
| Methodist church Prelate Samuel Kanu: Báyìí nì orí ṣé kò olórí ìjọ Methodist, àlùfáà méjì ní Abia yọ lọ́wọ́ ajínigbé | Ileeṣẹ ọlpaa ti fidi rẹ mulẹ awọn ajinigbe ti tu olori ijọ Methodist Samuel Kanu ti wọn jigbe ni Abia silẹ. Alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ naa lo ṣalaye ọrọ yi fun BBC. Amọ SP Geoffrey Ogbonna ko ṣalaye bi wọn se tu silẹ tabi boya wọn san owo idoola. Ni opin opin ọsẹ to kọja yi ni wọn ji olori ijọ yi gbe. Koda wọn ji alufa ijọ meji kan gbe pẹlu rẹ nigba ti wọn n dari bọ lati eto ile ijọsin kan to wa ni ipinlẹ Abia. Ọlọpaa ni awọn to wa pẹlu olori ijọ yi naa ti gba itusilẹ Awọn biṣọọbu meji to wa pẹlu rẹ ni Biṣọọbu ijọ Methodist Owerri Diocese, ati Prelate Chaplain ijọ naa. Olori kan ijọ eleto, Methodist Church of Nigeria, Ọmọwe Samuel Uche, ti di awati, lẹyin ti awọn kan ji gbe nipinlẹ Abia. Alukoro ọlọpaa nipinlẹ naa, Geoffrey Ogbonna, sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle, Channels Television pé, ọjọ Aiku ni iṣẹlẹ naa waye. Gẹ́gẹ́ bo ṣe sọ, ojisẹ Ọlọrun naa ati eeyan meji ni wọn ji gbé - Biṣọpu ìjọ Methodist ni Owerri,Rt. Rev. Dennis Mark, ati alufaa kan. Ogbonna salaye pe ni nkan bi aago meji ọsan ni wọn ji wọn gbe lasiko ti wọn kuro nibi ìsìn ìjọ kan nilu Okigwe nipinlẹ Imo, pada si ijọba ibilẹ Umu Nneochi nipinlẹ Abia. Àwọn agbébọn jí fadá ìjọ Kátólíkì méjì gbé ní Katsina "Akẹ́kọ̀ọ́ 1,440 ní iléẹ̀kọ́ 25 ni àwọn agbébọn ti jígbè lọ ní Naijiria" Kàyééfì! Àṣírí ìyá àti ọmọkùnrin rẹ̀, afurasi tó jí ọmọ ọlọ́mọ gbé fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó f'ọ́dún mẹ́ta tú l'Ekiti Agbẹnusọ ọlọpaa ni ijinigbe naa jẹ nkan tó buru pupọ, ṣùgbọ́n o ni idaniloju wa pe ileeṣẹ ọlọpaa ti n sakitiyan lati ri pe wọn pada sile laaye. Bákan naa lo rọ awọn araalu lati fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ti wọn ba kẹfin ohunkohun to le mu ki ominira awọn ojiṣẹ Ọlọ́run naa rọrun. Ọjọ diẹ sẹyin ni awọn agbebọ̀n pa ọmọ ile asofin kan nipinlẹ Anambra, Okechukwu Okoye. Wọn ti kọkọ ji Okoye gbe lọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun-un, ki awọn araalu to o ri oku rẹ lai ni orí. Shina Peller àti Teslim Folarin tahùn síra wọn lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn, wàhálà ṣẹlẹ̀ n'ídìbò abẹ́nú Oyo 'Ìdí rèé tí mo fi ń sin ẹkùn méjì nínú ilé mí' | Methodist church Prelate Samuel Kanu: Báyìí nì orí ṣé kò olórí ìjọ Methodist, àlùfáà méjì ní Abia yọ lọ́wọ́ ajínigbé Ileeṣẹ ọlpaa ti fidi rẹ mulẹ awọn ajinigbe ti tu olori ijọ Methodist Samuel Kanu ti wọn jigbe ni Abia silẹ. Alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ naa lo ṣalaye ọrọ yi fun BBC. Amọ SP Geoffrey Ogbonna ko ṣalaye bi wọn se tu silẹ tabi boya wọn san owo idoola. Ni opin opin ọsẹ to kọja yi ni wọn ji olori ijọ yi gbe. Koda wọn ji alufa ijọ meji kan gbe pẹlu rẹ nigba ti wọn n dari bọ lati eto ile ijọsin kan to wa ni ipinlẹ Abia. Ọlọpaa ni awọn to wa pẹlu olori ijọ yi naa ti gba itusilẹ Awọn biṣọọbu meji to wa pẹlu rẹ ni Biṣọọbu ijọ Methodist Owerri Diocese, ati Prelate Chaplain ijọ naa. Olori kan ijọ eleto, Methodist Church of Nigeria, Ọmọwe Samuel Uche, ti di awati, lẹyin ti awọn kan ji gbe nipinlẹ Abia. Alukoro ọlọpaa nipinlẹ naa, Geoffrey Ogbonna, sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle, Channels Television pé, ọjọ Aiku ni iṣẹlẹ naa waye. Gẹ́gẹ́ bo ṣe sọ, ojisẹ Ọlọrun naa ati eeyan meji ni wọn ji gbé - Biṣọpu ìjọ Methodist ni Owerri,Rt. Rev. Dennis Mark, ati alufaa kan. Ogbonna salaye pe ni nkan bi aago meji ọsan ni wọn ji wọn gbe lasiko ti wọn kuro nibi ìsìn ìjọ kan nilu Okigwe nipinlẹ Imo, pada si ijọba ibilẹ Umu Nneochi nipinlẹ Abia. Àwọn agbébọn jí fadá ìjọ Kátólíkì méjì gbé ní Katsina "Akẹ́kọ̀ọ́ 1,440 ní iléẹ̀kọ́ 25 ni àwọn agbébọn ti jígbè lọ ní Naijiria" Kàyééfì! Àṣírí ìyá àti ọmọkùnrin rẹ̀, afurasi tó jí ọmọ ọlọ́mọ gbé fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó f'ọ́dún mẹ́ta tú l'Ekiti Agbẹnusọ ọlọpaa ni ijinigbe naa jẹ nkan tó buru pupọ, ṣùgbọ́n o ni idaniloju wa pe ileeṣẹ ọlọpaa ti n sakitiyan lati ri pe wọn pada sile laaye. Bákan naa lo rọ awọn araalu lati fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ti wọn ba kẹfin ohunkohun to le mu ki ominira awọn ojiṣẹ Ọlọ́run naa rọrun. Ọjọ diẹ sẹyin ni awọn agbebọ̀n pa ọmọ ile asofin kan nipinlẹ Anambra, Okechukwu Okoye. Wọn ti kọkọ ji Okoye gbe lọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun-un, ki awọn araalu to o ri oku rẹ lai ni orí. Shina Peller àti Teslim Folarin tahùn síra wọn lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn, wàhálà ṣẹlẹ̀ n'ídìbò abẹ́nú Oyo 'Ìdí rèé tí mo fi ń sin ẹkùn méjì nínú ilé mí' | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61634478 |
2health
| “Mo mu ìtọ̀, mo jẹ èédú àti iyẹ̀pẹ̀ nítorí àìsàn ‘Ovarian cyst’ tó kọlù mí” | Obirin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Efezino Patrick, ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri fun BBC lẹyin ti aisan “Ovarian cyst” kọlu. Asiko ti Efezino ṣi wa ni ẹni ọdun mẹtala ni aisan naa ti bẹrẹ ko to bọ lọwọ aisan naa lẹyin ọdun mẹwaa gbako. Yatọ si awọn ohun ti aisan naa mu ko padanu, aisan ọhun tun mu ki idaduro de ba igbesi aye rẹ. O ni “Ọmọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni mi nigba ti aisan yii bẹrẹ, bẹẹ ni mo n gbe kiri titi de ile ẹkọ girama.” “Aisan naa mu ki ikun mi tobi, mo si n gbe ikun nla naa kiri to bẹẹ ti awọn akẹgbẹ mi nile ẹkọ maa n ṣe yẹyẹ mi nitori bi mo ṣe ri ninu ạṣọ ile ẹkọ naa.” Efezino ṣalaye pe ṣọọṣi ni wọn ti kọkọ sọ fun oun pe awọn kan fẹ fun oun ni majele jẹ ṣaaju aisan ọhun. O ni “Lọjọ kan bayii ni inu bẹrẹ si n dun mi, wọn gbe mi lọ sile iwosan ni Agbarho, amọ dokita sọ pe oun ko ri ohunkohun ninu mi, bẹẹ si ni inu ọhun bẹrẹ si n wu si.” “Ko si ibi ti iya mi ko de tan, bo ṣe n lọ sile iwosan naa lo n lọ sile awọn alagbo, to fi mọ oniruru ile ijọsin.” “Awọn kan tilẹ sọ pe ajẹ ni mi.” “Ko si ohun ti mi o mu ki aisan naa le lọ; bi mo ṣe n mu itọ mi naa ni mo n jẹ yẹpẹ, ti mo si n jẹ eedu.” Efezino ni ohun ṣi n lọ sile ẹkọ bo tilẹ jẹ pe aisan naa ko fun oun ni alaafia titi di igba ti ọga agba ile ẹkọ naa ni ki oun ma wa mọ. Gẹgẹ bi ohun to sọ, yatọ si ile ẹkọ oun to gba idaduro, oun ko to ẹni to n jade kuro ninu ile mọ. Efezino sọ pe bi awọn kan ṣe n pe oun ni iya ibeji ni awọn mii n pe oun ni ajẹ, bẹẹ naa ni awọn obi kan n ki awọn ọmọ wọn nilọ lati yago fun oun. Nipa ohun ti oju rẹ ri lasiko ti aisan naa n ba finra, Efezino sọ pe oun ko gbadura ki ọta oun ko irufẹ aisan naa lailai. Ẹwẹ, bo tilẹ jẹ pe lẹyin ọpọlọpọ ayẹwo, awọn dokita sọ fun Efezino pe aisan Ovarian Cyst lo kọlu, amọ o ni oun gbagbo pe iṣẹ awọn aye ni. Lẹyinorẹyin, wọn ṣe iṣẹ abẹ oni wakati mẹrin fun Efezino lati yọ ohun to wa ninu rẹ ohun, o si ni alaafia. Efezino sọ pe inu idunu ati ayọ ni oun wa bayii lẹyin iṣẹ abẹ naa, bẹẹ lo tun ṣalaye nipa awọn ohun ti oju rẹ ri lasiko aisan rẹ. O ni “Aisan naa lo da igbeyawo awọn obi mi ru, iya mi tun padanu owo rẹ, yatọ si awọn dukia to lu ni gbanjo loriṣiriṣi.” “Iya mi nikan lo duro ti mi ni gbogbo igba ti mo fi n dojukọ iṣoro naa.” “Awọn ẹgbọn mi, to fi mọ ọkọ iya mi naa ko fi mi silẹ nigba kọọkan.” Efezino sọ pe bayii, ni ṣe lo jọ bi pe wọn gbe ẹru wuwo kan kuro lori oun. O sọ pe “Ni bayii, mo le maa gbe igbe aye mi gẹgẹ bii awọn akẹgbẹ mi lai si wahala kankan.” “Iyatọ to kan wa nibẹ ni apa ti aisan naa ti da simi lara, amọ ko ṣe nnkan.” O ni oun nireti pe oun yoo ṣi pada sile ẹkọ laipẹ, amọ lọwọ yii oun ti n kọ iṣẹ awọn aṣaraloge ati ayaworan. | “Mo mu ìtọ̀, mo jẹ èédú àti iyẹ̀pẹ̀ nítorí àìsàn ‘Ovarian cyst’ tó kọlù mí” Obirin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Efezino Patrick, ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri fun BBC lẹyin ti aisan “Ovarian cyst” kọlu. Asiko ti Efezino ṣi wa ni ẹni ọdun mẹtala ni aisan naa ti bẹrẹ ko to bọ lọwọ aisan naa lẹyin ọdun mẹwaa gbako. Yatọ si awọn ohun ti aisan naa mu ko padanu, aisan ọhun tun mu ki idaduro de ba igbesi aye rẹ. O ni “Ọmọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni mi nigba ti aisan yii bẹrẹ, bẹẹ ni mo n gbe kiri titi de ile ẹkọ girama.” “Aisan naa mu ki ikun mi tobi, mo si n gbe ikun nla naa kiri to bẹẹ ti awọn akẹgbẹ mi nile ẹkọ maa n ṣe yẹyẹ mi nitori bi mo ṣe ri ninu ạṣọ ile ẹkọ naa.” Efezino ṣalaye pe ṣọọṣi ni wọn ti kọkọ sọ fun oun pe awọn kan fẹ fun oun ni majele jẹ ṣaaju aisan ọhun. O ni “Lọjọ kan bayii ni inu bẹrẹ si n dun mi, wọn gbe mi lọ sile iwosan ni Agbarho, amọ dokita sọ pe oun ko ri ohunkohun ninu mi, bẹẹ si ni inu ọhun bẹrẹ si n wu si.” “Ko si ibi ti iya mi ko de tan, bo ṣe n lọ sile iwosan naa lo n lọ sile awọn alagbo, to fi mọ oniruru ile ijọsin.” “Awọn kan tilẹ sọ pe ajẹ ni mi.” “Ko si ohun ti mi o mu ki aisan naa le lọ; bi mo ṣe n mu itọ mi naa ni mo n jẹ yẹpẹ, ti mo si n jẹ eedu.” Efezino ni ohun ṣi n lọ sile ẹkọ bo tilẹ jẹ pe aisan naa ko fun oun ni alaafia titi di igba ti ọga agba ile ẹkọ naa ni ki oun ma wa mọ. Gẹgẹ bi ohun to sọ, yatọ si ile ẹkọ oun to gba idaduro, oun ko to ẹni to n jade kuro ninu ile mọ. Efezino sọ pe bi awọn kan ṣe n pe oun ni iya ibeji ni awọn mii n pe oun ni ajẹ, bẹẹ naa ni awọn obi kan n ki awọn ọmọ wọn nilọ lati yago fun oun. Nipa ohun ti oju rẹ ri lasiko ti aisan naa n ba finra, Efezino sọ pe oun ko gbadura ki ọta oun ko irufẹ aisan naa lailai. Ẹwẹ, bo tilẹ jẹ pe lẹyin ọpọlọpọ ayẹwo, awọn dokita sọ fun Efezino pe aisan Ovarian Cyst lo kọlu, amọ o ni oun gbagbo pe iṣẹ awọn aye ni. Lẹyinorẹyin, wọn ṣe iṣẹ abẹ oni wakati mẹrin fun Efezino lati yọ ohun to wa ninu rẹ ohun, o si ni alaafia. Efezino sọ pe inu idunu ati ayọ ni oun wa bayii lẹyin iṣẹ abẹ naa, bẹẹ lo tun ṣalaye nipa awọn ohun ti oju rẹ ri lasiko aisan rẹ. O ni “Aisan naa lo da igbeyawo awọn obi mi ru, iya mi tun padanu owo rẹ, yatọ si awọn dukia to lu ni gbanjo loriṣiriṣi.” “Iya mi nikan lo duro ti mi ni gbogbo igba ti mo fi n dojukọ iṣoro naa.” “Awọn ẹgbọn mi, to fi mọ ọkọ iya mi naa ko fi mi silẹ nigba kọọkan.” Efezino sọ pe bayii, ni ṣe lo jọ bi pe wọn gbe ẹru wuwo kan kuro lori oun. O sọ pe “Ni bayii, mo le maa gbe igbe aye mi gẹgẹ bii awọn akẹgbẹ mi lai si wahala kankan.” “Iyatọ to kan wa nibẹ ni apa ti aisan naa ti da simi lara, amọ ko ṣe nnkan.” O ni oun nireti pe oun yoo ṣi pada sile ẹkọ laipẹ, amọ lọwọ yii oun ti n kọ iṣẹ awọn aṣaraloge ati ayaworan. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/c9ex14n04lko |
3politics
| Emefiele presidency ambition: Emefele kò lè ní kí INEC má bẹ́gi dínà èróngbà òun láti díje du ipò Ààre gẹ́gẹ́ bíi gómìnà CBN - Ilé ẹjọ́ | Emefele kò lè ní kí INEC má bẹ́gi dínà èróngbà òun láti díje du ipò Ààre gẹ́gẹ́ bíi gómìnà CBN - Ilé ẹjọ́ Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti kọ ẹbẹ gomina CBN, Godwin Emefiele, lati dẹkun ajọ eleto idibo, INEC, ati adajọ agba Naijiria, Abubakar Malami, lẹyin ti wọn gbe igbesẹ lati bẹgi dina ilepa rẹ lati dije du ipo Aarẹ Naijiria lai kọkọ fi ipo silẹ gẹgẹ bii gomina CBN. Emefiele sọ fun ile ẹjọ naa lọjọ Aje pe oun lẹtọ lati dije du ipo Aarẹ Naijiria lai kọkọ fi ipo silẹ gẹgẹ bii gomina banki apapọ, CBN. Kini o ṣẹlẹ nile ẹjọ́? Agbẹjọro Emefiele, Mike Ozekhome, sọ fun ile ẹjọ naa pe abala 84 (12) iwe ofin eto idibo "electoral act," ti wọn ṣe agbeyẹwo rẹ lọdun 2022 yii ko tako erongba onibara oun lati dije du ipo niwọn igba to jẹ pe oṣiṣẹ ijọba ni, kii ṣe ẹni ti wọn yan sipo nipasẹ oṣelu. Nigba to n ṣedajọ rẹ, ile ẹjọ giga naa ni ki adajọ agba Naijiria ati ajọ INEC yọju siwaju oun lọjọ kejila oṣu Karun un, lati wa ṣalaye eredi ti Emefiele ko fi le dije du ipo. Emefiele ni oun n fẹ ki ile ẹjọ naa kede pe o tọ si oun lati dije du ipo Aarẹ lai fi ipo silẹ. Ẹbẹ naa jẹ ọkan gboogi lara awọn ẹbẹ meje to gbe lọ siwaju ile ẹjọ ọhun. Yatọ si eyii, gomina CBN naa tun n fẹ ki ile ẹjọ kede pe oun lẹtọ labẹ ofin lati dibo fun ẹni ọkan oun ba n fẹ lọjọ idibo, yatọ si pe oun funra oun le dije du ipo. Emefiele tun n fẹ ki ile ẹjọ kede pe oun le kopa ninu ipade awọn oloṣelu ati lati kopa ninu eto ibibo abẹle wọn. Ẹwẹ, abala kẹsan an opfin CBN ti ọdun 2007 sọ pe gomina CBN ko gbọdọ ṣe iṣẹ miran lasiko to ba ṣi wa lori ipo gẹgẹ bii gomina CBN. Gómìnà báǹkì CBN, Emefiele ń lọ sí ilé ẹjọ́ lórí ilépa rẹ̀ láti di ààrẹ Gomina Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele ti gba ile ẹjọ lọ fun ile ẹjọ lati tumọ ofin to de e gẹgẹ bi gomina Banki naa ati ilepa rẹ lati dije fun ipo aarẹ lorilẹede Naijiria. Laipẹ yii ni awọn eeyan kan ko ara wọn jọ lati ra fọọmu ọlọgọrun miliọnu Naijiria fun Emefiele lati dije fun ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC. Iroyin n sọ pe ile ẹjọ giga apapọ Naijiria to wa nilu Abuja ni wọn gbe ẹjọ naa lọ. Oniruuru iha lawọn eeyan ti fihan si ipinnu gomina Banki apapọ Naijiria naa lati dije fun ipo aarẹ. Bi awọn kan ṣe n pariwo pe igbesẹ naa tako ilakalẹ ofin, paapaajulọ ofin ilana ihuwasi fun oṣiṣẹ ijọba lorilẹede Naijiria; ti wọn si n ke si Emefiele pe ko kọwe fipo rẹ silẹ bi o ba nifẹ si didu ipo aarẹ, tabi ki aarẹ Buhari funrarẹ o yọọ nipo. Iwe iroyin ojojumọ The Punch lorilẹede Naijiria fi iroyin kan sita pe alaga wọọdu kẹfa ni ijọba ibilẹ Ika South nipinlẹ Delta, nibi ti Emefiele ti ṣẹ wa ṣalaye pe fun awọn pe lootọ ati lododo ni gomina Banki apapọ Naijiria naa ti wa fi orukọ silẹ gẹgẹbi ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni wọọdu naa. "Bẹẹni, lati oṣu keji ọdun 2021 lo ti fi orukọ silẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ. Nitorina, ọmọ ẹgbẹ oṣelu wa ni. Ni ọjọ Satide ni gomina Banki apapọ naa ti fi sita loju ewe Twitter rẹ pe oun n reti itọni Ọlọrun lati mọ boya ki oun dije tabi ki oun wawọro. O ni oun yoo funra oun ra fọọmu ọlọgọrun miliọnu Nairati oun yoo fi dije. | Emefiele presidency ambition: Emefele kò lè ní kí INEC má bẹ́gi dínà èróngbà òun láti díje du ipò Ààre gẹ́gẹ́ bíi gómìnà CBN - Ilé ẹjọ́ Emefele kò lè ní kí INEC má bẹ́gi dínà èróngbà òun láti díje du ipò Ààre gẹ́gẹ́ bíi gómìnà CBN - Ilé ẹjọ́ Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti kọ ẹbẹ gomina CBN, Godwin Emefiele, lati dẹkun ajọ eleto idibo, INEC, ati adajọ agba Naijiria, Abubakar Malami, lẹyin ti wọn gbe igbesẹ lati bẹgi dina ilepa rẹ lati dije du ipo Aarẹ Naijiria lai kọkọ fi ipo silẹ gẹgẹ bii gomina CBN. Emefiele sọ fun ile ẹjọ naa lọjọ Aje pe oun lẹtọ lati dije du ipo Aarẹ Naijiria lai kọkọ fi ipo silẹ gẹgẹ bii gomina banki apapọ, CBN. Kini o ṣẹlẹ nile ẹjọ́? Agbẹjọro Emefiele, Mike Ozekhome, sọ fun ile ẹjọ naa pe abala 84 (12) iwe ofin eto idibo "electoral act," ti wọn ṣe agbeyẹwo rẹ lọdun 2022 yii ko tako erongba onibara oun lati dije du ipo niwọn igba to jẹ pe oṣiṣẹ ijọba ni, kii ṣe ẹni ti wọn yan sipo nipasẹ oṣelu. Nigba to n ṣedajọ rẹ, ile ẹjọ giga naa ni ki adajọ agba Naijiria ati ajọ INEC yọju siwaju oun lọjọ kejila oṣu Karun un, lati wa ṣalaye eredi ti Emefiele ko fi le dije du ipo. Emefiele ni oun n fẹ ki ile ẹjọ naa kede pe o tọ si oun lati dije du ipo Aarẹ lai fi ipo silẹ. Ẹbẹ naa jẹ ọkan gboogi lara awọn ẹbẹ meje to gbe lọ siwaju ile ẹjọ ọhun. Yatọ si eyii, gomina CBN naa tun n fẹ ki ile ẹjọ kede pe oun lẹtọ labẹ ofin lati dibo fun ẹni ọkan oun ba n fẹ lọjọ idibo, yatọ si pe oun funra oun le dije du ipo. Emefiele tun n fẹ ki ile ẹjọ kede pe oun le kopa ninu ipade awọn oloṣelu ati lati kopa ninu eto ibibo abẹle wọn. Ẹwẹ, abala kẹsan an opfin CBN ti ọdun 2007 sọ pe gomina CBN ko gbọdọ ṣe iṣẹ miran lasiko to ba ṣi wa lori ipo gẹgẹ bii gomina CBN. Gómìnà báǹkì CBN, Emefiele ń lọ sí ilé ẹjọ́ lórí ilépa rẹ̀ láti di ààrẹ Gomina Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele ti gba ile ẹjọ lọ fun ile ẹjọ lati tumọ ofin to de e gẹgẹ bi gomina Banki naa ati ilepa rẹ lati dije fun ipo aarẹ lorilẹede Naijiria. Laipẹ yii ni awọn eeyan kan ko ara wọn jọ lati ra fọọmu ọlọgọrun miliọnu Naijiria fun Emefiele lati dije fun ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC. Iroyin n sọ pe ile ẹjọ giga apapọ Naijiria to wa nilu Abuja ni wọn gbe ẹjọ naa lọ. Oniruuru iha lawọn eeyan ti fihan si ipinnu gomina Banki apapọ Naijiria naa lati dije fun ipo aarẹ. Bi awọn kan ṣe n pariwo pe igbesẹ naa tako ilakalẹ ofin, paapaajulọ ofin ilana ihuwasi fun oṣiṣẹ ijọba lorilẹede Naijiria; ti wọn si n ke si Emefiele pe ko kọwe fipo rẹ silẹ bi o ba nifẹ si didu ipo aarẹ, tabi ki aarẹ Buhari funrarẹ o yọọ nipo. Iwe iroyin ojojumọ The Punch lorilẹede Naijiria fi iroyin kan sita pe alaga wọọdu kẹfa ni ijọba ibilẹ Ika South nipinlẹ Delta, nibi ti Emefiele ti ṣẹ wa ṣalaye pe fun awọn pe lootọ ati lododo ni gomina Banki apapọ Naijiria naa ti wa fi orukọ silẹ gẹgẹbi ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni wọọdu naa. "Bẹẹni, lati oṣu keji ọdun 2021 lo ti fi orukọ silẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ. Nitorina, ọmọ ẹgbẹ oṣelu wa ni. Ni ọjọ Satide ni gomina Banki apapọ naa ti fi sita loju ewe Twitter rẹ pe oun n reti itọni Ọlọrun lati mọ boya ki oun dije tabi ki oun wawọro. O ni oun yoo funra oun ra fọọmu ọlọgọrun miliọnu Nairati oun yoo fi dije. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61376412 |
3politics
| PDP youth leader jailed: Bí Kato ṣe d'èrò ẹ̀wọ̀n torí ó bú Buhari, Boss Mustapha | Ile ẹjọ́ Majisireeti kan ni Yola, Ìpínlẹ̀ Adamawa tí dajọ pé wọn rán olórí àwọn ọdọ lẹgbẹ òṣèlú Peoples Democratic Party ni ijoba ibile Hong, tí orúkọ rẹ ń jẹ Ikamu Kanto lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan gbáko. O ri ẹwọn he látàrí pé ó sọ̀rọ̀ àbùkù sì Ààrẹ Naijiria, Ogagun Muhammadu Buhari ati akọ̀wé ijoba àpapọ̀, Boss Mustapha. Àwọn iwe iroyin sọ pé wọn fi olórí ọdọ náà sì ẹ̀wọ̀n lórí esun kan tí àwọn alatileyin akọ̀wé àgbà ijoba àpapọ̀ fi kan an lábẹ́ aburada ẹgbẹ́ to ń jẹ "Adamawa Concerned Citizens" èyí tí Husseini Gambo dárí. Ní ọ̀sẹ̀ to koja, wọn pé Kato kò wá kawọ ponyin ro ẹjọ́ nípasẹ̀ ọ́fíìsì àjọ Otelemuye DSS nípasẹ̀ ọ́fíìsì Agbejoro àgbà. Kato sọ pé nítorí ìbínú bí ikọ Boko Haram ṣe kọlu ìlú Dabna níbi tí èèyàn tó lè ní ogún ti padanu ẹ̀mí wọn lo mu ki òun bọ si oju òpó Facebook láti fun pe sì akowe àgbà àti Ààrẹ Buhari. O ni ki wọn le tun tẹsiwaju lori pipese eto aabo to peye ni. O tun ni lórí kikuna láti dá abo bo ẹ̀mí àwọn olùgbé ìlú náà tó jẹ́ ijoba ìbílẹ̀ tìrẹ to sì tún jẹ́ ibi tí akowe àgbà náà tí wá Lẹyin tí adajọ Majisireeti náà, Dimas Elishama gbọ́ ẹjọ́ náà, ó ní Kato jẹbi ẹ̀sùn tí wọn fi kan an ó sì rán án lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdun kan pelu faani egberun meedogbon náírà fún pé ó lo àwọn ọ̀rọ̀ àbùkù àti alufansa. Ilé ẹjọ́ ni àwọn tí gbó ẹ̀bẹ̀ rẹ pé kí àwọn fi ojú àánú wo ọrọ náà, wọn tún wo ìhùwàsí rẹ lásìkò ẹjọ́ náà ni wọn ba fi kún un pé kò ní lọ lai jìyà sugbọn yóò jìyà láti jẹ àpẹrẹ fún àwọn tó kú. | PDP youth leader jailed: Bí Kato ṣe d'èrò ẹ̀wọ̀n torí ó bú Buhari, Boss Mustapha Ile ẹjọ́ Majisireeti kan ni Yola, Ìpínlẹ̀ Adamawa tí dajọ pé wọn rán olórí àwọn ọdọ lẹgbẹ òṣèlú Peoples Democratic Party ni ijoba ibile Hong, tí orúkọ rẹ ń jẹ Ikamu Kanto lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan gbáko. O ri ẹwọn he látàrí pé ó sọ̀rọ̀ àbùkù sì Ààrẹ Naijiria, Ogagun Muhammadu Buhari ati akọ̀wé ijoba àpapọ̀, Boss Mustapha. Àwọn iwe iroyin sọ pé wọn fi olórí ọdọ náà sì ẹ̀wọ̀n lórí esun kan tí àwọn alatileyin akọ̀wé àgbà ijoba àpapọ̀ fi kan an lábẹ́ aburada ẹgbẹ́ to ń jẹ "Adamawa Concerned Citizens" èyí tí Husseini Gambo dárí. Ní ọ̀sẹ̀ to koja, wọn pé Kato kò wá kawọ ponyin ro ẹjọ́ nípasẹ̀ ọ́fíìsì àjọ Otelemuye DSS nípasẹ̀ ọ́fíìsì Agbejoro àgbà. Kato sọ pé nítorí ìbínú bí ikọ Boko Haram ṣe kọlu ìlú Dabna níbi tí èèyàn tó lè ní ogún ti padanu ẹ̀mí wọn lo mu ki òun bọ si oju òpó Facebook láti fun pe sì akowe àgbà àti Ààrẹ Buhari. O ni ki wọn le tun tẹsiwaju lori pipese eto aabo to peye ni. O tun ni lórí kikuna láti dá abo bo ẹ̀mí àwọn olùgbé ìlú náà tó jẹ́ ijoba ìbílẹ̀ tìrẹ to sì tún jẹ́ ibi tí akowe àgbà náà tí wá Lẹyin tí adajọ Majisireeti náà, Dimas Elishama gbọ́ ẹjọ́ náà, ó ní Kato jẹbi ẹ̀sùn tí wọn fi kan an ó sì rán án lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdun kan pelu faani egberun meedogbon náírà fún pé ó lo àwọn ọ̀rọ̀ àbùkù àti alufansa. Ilé ẹjọ́ ni àwọn tí gbó ẹ̀bẹ̀ rẹ pé kí àwọn fi ojú àánú wo ọrọ náà, wọn tún wo ìhùwàsí rẹ lásìkò ẹjọ́ náà ni wọn ba fi kún un pé kò ní lọ lai jìyà sugbọn yóò jìyà láti jẹ àpẹrẹ fún àwọn tó kú. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58079951 |
4religion
| COZA: Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ni ṣọ́ọ́ṣì COZA láàrọ́ yìí | Saaju ni Busola Dakolo aya gbajugbaja olorin Timi Dakolo fẹsun kan Pasitọ Biodun Fatoyinbo ti ijọ COZA pe o fipa ba oun lo pọ nigba kan. Lẹyin eyi ni ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria sọrọ sita pe iwa ifipabanilopọ gbọdọ di ohun igbagbe ni awujọ wa. Pasito Biodun Fatoyinbo to da ijọ COZA silẹ fi atẹjadee sita pe irọ ni ẹsun naa nitori oun ko fipa ba ẹnikẹni lo pọ ri laye ounCOZA: Mi ò fípá bá obìrin lò pọ̀ rí láyé mi - Pásítọ̀ Fatoyinbo. Awọn obinrin ti pejọ pọ siwaju ijọ COZA ni Guzape ni Asokoro ni Abuja to jẹ olu ilu Naijiria fún iwọde lori ọrọ ifipabanilopọ. Ni ipinlẹ Eko, awọn eniyan ti n korajọ pọ lati ṣe iwọde lodi si ifipabanilopọ. Opopona Mobolaji Bank Anthony ti ijọ COZA wa ni ipinlẹ Eko ni wọn pejọ pọ si fi n ṣe iwọde pe ko yẹ ki a gbọ iru eyi ninu ijọ Olorun. Àwọn agbofinro ti dé sí ṣọ̀ọ̀sì COZA ni Eko. Àwọn agbofinro ti dé sí ṣọ̀ọ̀sì COZA ni Eko Ojo ti bẹrẹ ni Ikeja nibi ti awọn eniyan ko ara wọn jọ si lati ṣe iwọde lori ọrọ ifipabanilopọ adari ijọ COZA. Gbogbo awon to jade ninu ojo ni Eko n pariwo 'No to Rape' ni. Ariwo " No to Rape" ni àwọn olùwọ́de ń pa nipinlẹ Eko nínú òjò. Ero pupọ lo ti kun ita ile ijọsin Commonwealth of Zion Assembly nipinlẹ Eko. Iroyin to n kan BBC lọwọ ni pe awọn ọmọ ijọ COZA nikan ni wọn n jẹ ko wọle inu ile ijọsin laarọ yii lati jọsin. Iroyin ni, wọn n beere ibeere nipa ijọ naa lọwọ awọn olujọsin to n wọle ki wọn le mọ boya ọmọ ijọ ni wọn ni tootọ ki wọn to jẹ ki wọn wọle. Bakan naa ni wọn tun n lo àwọn ami idanimọ ara ọkọ ayokẹlẹ fi da ogidi ọmọ ijọ mọ. Awọn ikọ #Churchtoo ni wọn n ṣeto iwọde ti Abuja ti wọn fi ni ki pasitọ Fatoyinbo fipo rẹ silẹ. Loju ti wọn, wọn gba pe ko yẹ ki ẹsun ifipabanilopọ jade ni ile ijọ Olorun rara. 'Pasitọ rẹ kìí ṣe Olorun rẹ' ni àkọ́lé ìwọ́de kan ni Abuja. Iroyin ni sibẹ awọn olujọsin n wọ lọ sile ijọsin COZA ni nitori igbagbọ wọn. Eyi ni iroyin tuntun to jade pe awọn agbofinro Àwọn agbófinró ń gba ńkan sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olùjọ́sìn ni COZA Abuja bii iwe jọ́tà, atawọn ohun eelo ikọwe silẹ. Bakan naa ni iroyin to n tẹ wa lọwọ nsiyi sọ pe awọn oṣiṣẹ ni ijọ COZA ni Abuja ti duro lati ma fi aaye gba awọn oluwọde lati wọle rara. Modele Fatoyinbo to jẹ iyawo Pasitọ Biodun Fatoyinbo ti wọn fẹsun kan lori ifipabanilopo ti sọrọ. O ni ọkọ oun ko lee fipa ba ẹnikẹni lo pọ nitori oun jẹri ọkọ oun. Awọn oluwọde n hó lé awọn ọmọ ijọ COZa lori ni Eko bi wọn ṣe n tu jade. Isin oni ti pari ni COZA nigba ti Pasitọ Biodun Fatoyinbo ba awọn ọmọ ijọ sọrọ. Àwọn olùwọ́de ń hó lé àwọn ọmọ ijọ COZA ni Eko bi wọ́n ṣe n jáde. Modele Fatoyinbo, ìyàwó Biodun Fatoyinbo ti wọn fẹ́sùn kàn ni COZA ni kò ṣeéṣe fún ọkọ òun láti fipá bá ẹnikeni lòpọ̀. Nigba ti Pasitọ Biodun Fatoyinbo de sinu ijọ loni, o ki gbogbo awọn eniyan rẹ ku aduroti lasiko yii. O gba wọn nimọran lati ma fun ẹnikẹni lesi nipa iṣẹlẹ ẹsun yii. Sugbon ko waasu rara ninu isin toni. O ni oun ti fa ọrọ ẹsun naa le awọn agba igbimo ijọ lati ṣe iwadii to yẹ ati awọn ẹni iwaju ti oun n wo. | COZA: Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ni ṣọ́ọ́ṣì COZA láàrọ́ yìí Saaju ni Busola Dakolo aya gbajugbaja olorin Timi Dakolo fẹsun kan Pasitọ Biodun Fatoyinbo ti ijọ COZA pe o fipa ba oun lo pọ nigba kan. Lẹyin eyi ni ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria sọrọ sita pe iwa ifipabanilopọ gbọdọ di ohun igbagbe ni awujọ wa. Pasito Biodun Fatoyinbo to da ijọ COZA silẹ fi atẹjadee sita pe irọ ni ẹsun naa nitori oun ko fipa ba ẹnikẹni lo pọ ri laye ounCOZA: Mi ò fípá bá obìrin lò pọ̀ rí láyé mi - Pásítọ̀ Fatoyinbo. Awọn obinrin ti pejọ pọ siwaju ijọ COZA ni Guzape ni Asokoro ni Abuja to jẹ olu ilu Naijiria fún iwọde lori ọrọ ifipabanilopọ. Ni ipinlẹ Eko, awọn eniyan ti n korajọ pọ lati ṣe iwọde lodi si ifipabanilopọ. Opopona Mobolaji Bank Anthony ti ijọ COZA wa ni ipinlẹ Eko ni wọn pejọ pọ si fi n ṣe iwọde pe ko yẹ ki a gbọ iru eyi ninu ijọ Olorun. Àwọn agbofinro ti dé sí ṣọ̀ọ̀sì COZA ni Eko. Àwọn agbofinro ti dé sí ṣọ̀ọ̀sì COZA ni Eko Ojo ti bẹrẹ ni Ikeja nibi ti awọn eniyan ko ara wọn jọ si lati ṣe iwọde lori ọrọ ifipabanilopọ adari ijọ COZA. Gbogbo awon to jade ninu ojo ni Eko n pariwo 'No to Rape' ni. Ariwo " No to Rape" ni àwọn olùwọ́de ń pa nipinlẹ Eko nínú òjò. Ero pupọ lo ti kun ita ile ijọsin Commonwealth of Zion Assembly nipinlẹ Eko. Iroyin to n kan BBC lọwọ ni pe awọn ọmọ ijọ COZA nikan ni wọn n jẹ ko wọle inu ile ijọsin laarọ yii lati jọsin. Iroyin ni, wọn n beere ibeere nipa ijọ naa lọwọ awọn olujọsin to n wọle ki wọn le mọ boya ọmọ ijọ ni wọn ni tootọ ki wọn to jẹ ki wọn wọle. Bakan naa ni wọn tun n lo àwọn ami idanimọ ara ọkọ ayokẹlẹ fi da ogidi ọmọ ijọ mọ. Awọn ikọ #Churchtoo ni wọn n ṣeto iwọde ti Abuja ti wọn fi ni ki pasitọ Fatoyinbo fipo rẹ silẹ. Loju ti wọn, wọn gba pe ko yẹ ki ẹsun ifipabanilopọ jade ni ile ijọ Olorun rara. 'Pasitọ rẹ kìí ṣe Olorun rẹ' ni àkọ́lé ìwọ́de kan ni Abuja. Iroyin ni sibẹ awọn olujọsin n wọ lọ sile ijọsin COZA ni nitori igbagbọ wọn. Eyi ni iroyin tuntun to jade pe awọn agbofinro Àwọn agbófinró ń gba ńkan sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olùjọ́sìn ni COZA Abuja bii iwe jọ́tà, atawọn ohun eelo ikọwe silẹ. Bakan naa ni iroyin to n tẹ wa lọwọ nsiyi sọ pe awọn oṣiṣẹ ni ijọ COZA ni Abuja ti duro lati ma fi aaye gba awọn oluwọde lati wọle rara. Modele Fatoyinbo to jẹ iyawo Pasitọ Biodun Fatoyinbo ti wọn fẹsun kan lori ifipabanilopo ti sọrọ. O ni ọkọ oun ko lee fipa ba ẹnikẹni lo pọ nitori oun jẹri ọkọ oun. Awọn oluwọde n hó lé awọn ọmọ ijọ COZa lori ni Eko bi wọn ṣe n tu jade. Isin oni ti pari ni COZA nigba ti Pasitọ Biodun Fatoyinbo ba awọn ọmọ ijọ sọrọ. Àwọn olùwọ́de ń hó lé àwọn ọmọ ijọ COZA ni Eko bi wọ́n ṣe n jáde. Modele Fatoyinbo, ìyàwó Biodun Fatoyinbo ti wọn fẹ́sùn kàn ni COZA ni kò ṣeéṣe fún ọkọ òun láti fipá bá ẹnikeni lòpọ̀. Nigba ti Pasitọ Biodun Fatoyinbo de sinu ijọ loni, o ki gbogbo awọn eniyan rẹ ku aduroti lasiko yii. O gba wọn nimọran lati ma fun ẹnikẹni lesi nipa iṣẹlẹ ẹsun yii. Sugbon ko waasu rara ninu isin toni. O ni oun ti fa ọrọ ẹsun naa le awọn agba igbimo ijọ lati ṣe iwadii to yẹ ati awọn ẹni iwaju ti oun n wo. | https://www.bbc.com/yoruba/48815820 |
2health
| DNA: Njẹ́ o mọ pé obìnrin lè bí Ìbejì tí wọ́n yóò sì ní bàbá ọtọ́ọ̀tọ̀? | Taiwo ati Kehinde Olanrewaju (kii ṣe orukọ wọn gangan ree) jẹ ọmọ meji akọkọ ti obi wọn bi. Nipa ti jijọ, wọn ko foju jọ ara wọn to bẹẹ ṣugbọn eleyi ko jẹ tuntun nitori awọn ibeji mi wa to jẹ pe wọn kii jọ ara wọn. Nigba ti wọn wa lọmọ ọdun mẹfa, Kehinde farapa ti wọn si nilo lati ṣe iṣẹ abẹ fun. Iṣẹ abẹ naa nilo ki wọn gba ẹya ara baba rẹ kan, ki o to le gbadun. Awọn dokita ṣetan, wọn ṣe ayẹwo baba rẹ ṣugbọn wọn ri wi pe ẹya rẹ ko papọ mọ ti Kehinde. Nkechi Blessing: Mi ò gbá ẹ mú nígbà tóo dákú níbí ìsìnkú Mama Nkechi tórí ... - Toyin Abraham Báyìí ni mo ṣe san nínú oore Ọlọ́run tó fi Kábíyèsì Ooni ti Ile Ife ta èmi Silekunola lọ́rẹ - Olorì Wòlíì Naomi Àwọn obìnrin ń ṣe igbéyàwó pẹ̀lú igi láti ṣààmì ètò ìdàgbàsókè ìlú wọn Ọrọ naa ṣe wọn ni kayeefi, ti o si mu ki baba Kehinde maa beere pe bawo leyi ti ṣe jẹ. Asẹyinwa aṣẹyinbọ, wọn ṣayẹwọ DNA fun Kehinde, ti wọn si ri wi pe kii ṣe ọmọ baba rẹ ṣugbọn ayẹwo fihan pe oun lo bi Taiye. Njẹ eeyan le bi ibeji fun baba ọtọọtọ? Nigba ti wọn n salaye bi eyi se ri bẹẹ, awọn dokita ni o ṣeese ki o ṣẹlẹ bẹẹ niwọn igba ti iya awọn ọmọ naa ba ni ibalopọ pẹlu awọn ọkunrin meji lasiko kan naa ṣaaju ki o to loyun. Wọn ni iru iṣẹlẹ yii ṣọwọn amọ o le ṣẹlẹ. Orukọ ti wọn pe iru isẹlẹ yi ni ede gẹẹsi ni ‘Heteropaternalsuperfecundation’. Bawo lo ṣe n ṣẹlẹ: Awọn onimọ ṣayensi fidi ọrọ mulẹ pe, iṣẹlẹ superfecundationis yii ṣọwọn laarin awọn eeyan ṣugbọn lagbo ẹranko, iru rẹ a maa wọpọ daadaa. Ni ṣoki, oun to ṣẹlẹ ni pe, àtọ̀ orisi meji ọtọọtọ ni yoo dapọ mọ ẹyin obinrin lasiko ibalopọ ọtọọtọ, ti yoo si bi ibeji lati ara ọkunrin ọtọọtọ. Iru iṣẹlẹ yii kan naa to waye ni orileedẹ Vietnam lọdun 2016, Ọjọgbọn Le Dinh Luong, to jẹ aarẹ awọn onimọ ẹya ara Vietnam Genetic Association, ṣayẹwo awọn ibeji kan ti wọn ko foju jọ ara wọn, to si fidi ọrọ mulẹ pe wọn kii ṣe ọmọ baba kan naa. O ni iru iṣẹlẹ yi ko wọpọ ''koda o ni awọn ibeji to ni baba ọtọọtọ bayii ko ju mẹwa lọ tawọn mọ lagbaye'' O tẹsiwaju pe, o ṣeeṣe ki awọn mii wa ṣugbọn tawọn obi wọn ko mọ pe baba ọtọọtọ lo bi wọn tabi ki wọn si maa fẹ pariwo rẹ faraye gbọ. Awọn onimọ tẹsiwaju pe, ki iru nkan bayii to le ṣẹlẹ yoo jẹ wi pe, ẹyin meji ọtọọtọ to n dọmọ lara obinrin ni yoo wa ninu ile ọmọ obinrin naa, ti aatọ awọn ọkunrin mejeeji to ba ba lopọ lasiko kan naa, yoo si da pọ mọ wọn lọtọọtọ. O tun le ṣẹlẹ ti ile ọmọ obinrin ba pese ẹyin lẹẹmeeji lera wọn, ti awọn ẹyin ọtọọtọ yii ba si dapọ mọ aatọ ọkunrin meji ọtọọtọ to ni ibalopọ pẹlu obinrin naa. Ti adura ba gba ti o di oyun, oun ti yoo ṣẹlẹ ni pe awọn ọmọ meji pẹlu baba ọtọọtọ ni obinrin naa yoo bi. Yatọ si iṣẹlẹ ta fidi rẹ mulẹ pe o waye ni Vietnam lọdun 2016, awọn irufẹ iṣẹlẹ yii to waye ni ti ilẹ Amẹrika nilu New Jersey lọdun 2015. Ibeji obinrin lawọn ọmọ yii, awọn si ni ikẹta irufẹ isẹlẹ yii ti akọsilẹ wa pe o ṣẹlẹ ni Amẹrika. Awọn irufẹ isẹlẹ mii to tun waye ni ti orileede Turkey nibi ti awọn ileeṣẹ iroyin ni awọn ibeji kan ni baba ọtọọtọ lọdun 2010. Apejuwe la fi wọn ṣe ṣugbọn ko tumọ si pe ko le ṣẹlẹ ni Naijiria naa. Taa n tiẹ mọ boya iru rẹ ti waye ṣugbọn tawọn mọlẹbi ko kan fẹ polongo ṣetigbọ araye. | DNA: Njẹ́ o mọ pé obìnrin lè bí Ìbejì tí wọ́n yóò sì ní bàbá ọtọ́ọ̀tọ̀? Taiwo ati Kehinde Olanrewaju (kii ṣe orukọ wọn gangan ree) jẹ ọmọ meji akọkọ ti obi wọn bi. Nipa ti jijọ, wọn ko foju jọ ara wọn to bẹẹ ṣugbọn eleyi ko jẹ tuntun nitori awọn ibeji mi wa to jẹ pe wọn kii jọ ara wọn. Nigba ti wọn wa lọmọ ọdun mẹfa, Kehinde farapa ti wọn si nilo lati ṣe iṣẹ abẹ fun. Iṣẹ abẹ naa nilo ki wọn gba ẹya ara baba rẹ kan, ki o to le gbadun. Awọn dokita ṣetan, wọn ṣe ayẹwo baba rẹ ṣugbọn wọn ri wi pe ẹya rẹ ko papọ mọ ti Kehinde. Nkechi Blessing: Mi ò gbá ẹ mú nígbà tóo dákú níbí ìsìnkú Mama Nkechi tórí ... - Toyin Abraham Báyìí ni mo ṣe san nínú oore Ọlọ́run tó fi Kábíyèsì Ooni ti Ile Ife ta èmi Silekunola lọ́rẹ - Olorì Wòlíì Naomi Àwọn obìnrin ń ṣe igbéyàwó pẹ̀lú igi láti ṣààmì ètò ìdàgbàsókè ìlú wọn Ọrọ naa ṣe wọn ni kayeefi, ti o si mu ki baba Kehinde maa beere pe bawo leyi ti ṣe jẹ. Asẹyinwa aṣẹyinbọ, wọn ṣayẹwọ DNA fun Kehinde, ti wọn si ri wi pe kii ṣe ọmọ baba rẹ ṣugbọn ayẹwo fihan pe oun lo bi Taiye. Njẹ eeyan le bi ibeji fun baba ọtọọtọ? Nigba ti wọn n salaye bi eyi se ri bẹẹ, awọn dokita ni o ṣeese ki o ṣẹlẹ bẹẹ niwọn igba ti iya awọn ọmọ naa ba ni ibalopọ pẹlu awọn ọkunrin meji lasiko kan naa ṣaaju ki o to loyun. Wọn ni iru iṣẹlẹ yii ṣọwọn amọ o le ṣẹlẹ. Orukọ ti wọn pe iru isẹlẹ yi ni ede gẹẹsi ni ‘Heteropaternalsuperfecundation’. Bawo lo ṣe n ṣẹlẹ: Awọn onimọ ṣayensi fidi ọrọ mulẹ pe, iṣẹlẹ superfecundationis yii ṣọwọn laarin awọn eeyan ṣugbọn lagbo ẹranko, iru rẹ a maa wọpọ daadaa. Ni ṣoki, oun to ṣẹlẹ ni pe, àtọ̀ orisi meji ọtọọtọ ni yoo dapọ mọ ẹyin obinrin lasiko ibalopọ ọtọọtọ, ti yoo si bi ibeji lati ara ọkunrin ọtọọtọ. Iru iṣẹlẹ yii kan naa to waye ni orileedẹ Vietnam lọdun 2016, Ọjọgbọn Le Dinh Luong, to jẹ aarẹ awọn onimọ ẹya ara Vietnam Genetic Association, ṣayẹwo awọn ibeji kan ti wọn ko foju jọ ara wọn, to si fidi ọrọ mulẹ pe wọn kii ṣe ọmọ baba kan naa. O ni iru iṣẹlẹ yi ko wọpọ ''koda o ni awọn ibeji to ni baba ọtọọtọ bayii ko ju mẹwa lọ tawọn mọ lagbaye'' O tẹsiwaju pe, o ṣeeṣe ki awọn mii wa ṣugbọn tawọn obi wọn ko mọ pe baba ọtọọtọ lo bi wọn tabi ki wọn si maa fẹ pariwo rẹ faraye gbọ. Awọn onimọ tẹsiwaju pe, ki iru nkan bayii to le ṣẹlẹ yoo jẹ wi pe, ẹyin meji ọtọọtọ to n dọmọ lara obinrin ni yoo wa ninu ile ọmọ obinrin naa, ti aatọ awọn ọkunrin mejeeji to ba ba lopọ lasiko kan naa, yoo si da pọ mọ wọn lọtọọtọ. O tun le ṣẹlẹ ti ile ọmọ obinrin ba pese ẹyin lẹẹmeeji lera wọn, ti awọn ẹyin ọtọọtọ yii ba si dapọ mọ aatọ ọkunrin meji ọtọọtọ to ni ibalopọ pẹlu obinrin naa. Ti adura ba gba ti o di oyun, oun ti yoo ṣẹlẹ ni pe awọn ọmọ meji pẹlu baba ọtọọtọ ni obinrin naa yoo bi. Yatọ si iṣẹlẹ ta fidi rẹ mulẹ pe o waye ni Vietnam lọdun 2016, awọn irufẹ iṣẹlẹ yii to waye ni ti ilẹ Amẹrika nilu New Jersey lọdun 2015. Ibeji obinrin lawọn ọmọ yii, awọn si ni ikẹta irufẹ isẹlẹ yii ti akọsilẹ wa pe o ṣẹlẹ ni Amẹrika. Awọn irufẹ isẹlẹ mii to tun waye ni ti orileede Turkey nibi ti awọn ileeṣẹ iroyin ni awọn ibeji kan ni baba ọtọọtọ lọdun 2010. Apejuwe la fi wọn ṣe ṣugbọn ko tumọ si pe ko le ṣẹlẹ ni Naijiria naa. Taa n tiẹ mọ boya iru rẹ ti waye ṣugbọn tawọn mọlẹbi ko kan fẹ polongo ṣetigbọ araye. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-55607742 |
2health
| Sexual Abstinence: Ṣé lóòtọ́ ni àìní ìbálòpọ̀ lfún ìgbà pípẹ́ yóò sẹ àkóbá fún ara rẹ? | Lootọ ni ibalopọ laarin ọkunrin ati obinrin jẹ nkan to ni adun pupọ, to si ma n mu ara ya daada, ṣugbọn bo sẹ dun to, awọn kan pinnu lati mu ara duro fun asiko kan. Imọ ijinlẹ sayẹnsi fihan pe ọpọlọpọ anfaani lo wa ninu ibalopọ loore-koore fun awọn ololufẹ. Igbagbọ awọn eeyan kan ni pe o lewu fun ẹni ti ko ba ni ibalopọ fun ọjọ pipẹ, to si le koba ilera ara wọn. Ṣugbọn ṣe lootọ ni? Iwadii kan ti BBC Igbo ṣe nipa ifọrọwanilẹnuwo pẹlu dokita onimọ iṣegun oyinbo kan, Udodi Okoli dahun ibeere yii. Dokita Okoli sọ pe imọ sayẹnsi ko tii sọ boya ewu kankan wa fun ilera ẹnikẹni ti ko ba ni ibalopọ . O ni nkan ṣoṣo ti sayẹnsi sọ ni pe o le nipa lori ironu iru ẹni bẹ́ẹ̀, paapaa nitori bi awọn eeyan ṣe le ma a fi ẹni naa ṣe yẹyẹ. Lara anfaani ibalopọ gẹgẹ bi dokita ṣe sọ ni pe, o ma n mu ki ara eeyan sinmi lẹyin wahala. Dokita miran, Malik Haruna King sọ pe ko si nkan to buru ninu ki eeyan pinnu pe oun ko fẹ ni ibalopọ. Iru ẹni naa ko le ni wahala kankan ni agọ ara rẹ. "Koda, obinrin tabi ọkunrin ti ko ba ni ibalopọ fun igba pipẹ, yoo gbe igbeaye to dara bi awọn to n ni ibalopọ. Dokita Okoli sọ pe irọ patapata ni bi awọn kan sẹ ma n sọ pe ọkunrin ti kii ba ni ibalopọ rara tabi ni igba gbogbo yoo ni jẹjẹrẹ ni koropọn rẹ, Okoli sọ pe yatọ si ibalopọ pẹlu obinrin, awọn ọkunrin ma n da atọ loju orun, eyi ti awọn oni Gẹẹsi n pe ni 'Wet Dream'. Fun obinrin, ọ̀kan lara kudiẹ-kudiẹ to wa ninu aini ibalopọ fun igba pipẹ ni pe o le fa irora nigba to ba fẹ ẹ ni. | Sexual Abstinence: Ṣé lóòtọ́ ni àìní ìbálòpọ̀ lfún ìgbà pípẹ́ yóò sẹ àkóbá fún ara rẹ? Lootọ ni ibalopọ laarin ọkunrin ati obinrin jẹ nkan to ni adun pupọ, to si ma n mu ara ya daada, ṣugbọn bo sẹ dun to, awọn kan pinnu lati mu ara duro fun asiko kan. Imọ ijinlẹ sayẹnsi fihan pe ọpọlọpọ anfaani lo wa ninu ibalopọ loore-koore fun awọn ololufẹ. Igbagbọ awọn eeyan kan ni pe o lewu fun ẹni ti ko ba ni ibalopọ fun ọjọ pipẹ, to si le koba ilera ara wọn. Ṣugbọn ṣe lootọ ni? Iwadii kan ti BBC Igbo ṣe nipa ifọrọwanilẹnuwo pẹlu dokita onimọ iṣegun oyinbo kan, Udodi Okoli dahun ibeere yii. Dokita Okoli sọ pe imọ sayẹnsi ko tii sọ boya ewu kankan wa fun ilera ẹnikẹni ti ko ba ni ibalopọ . O ni nkan ṣoṣo ti sayẹnsi sọ ni pe o le nipa lori ironu iru ẹni bẹ́ẹ̀, paapaa nitori bi awọn eeyan ṣe le ma a fi ẹni naa ṣe yẹyẹ. Lara anfaani ibalopọ gẹgẹ bi dokita ṣe sọ ni pe, o ma n mu ki ara eeyan sinmi lẹyin wahala. Dokita miran, Malik Haruna King sọ pe ko si nkan to buru ninu ki eeyan pinnu pe oun ko fẹ ni ibalopọ. Iru ẹni naa ko le ni wahala kankan ni agọ ara rẹ. "Koda, obinrin tabi ọkunrin ti ko ba ni ibalopọ fun igba pipẹ, yoo gbe igbeaye to dara bi awọn to n ni ibalopọ. Dokita Okoli sọ pe irọ patapata ni bi awọn kan sẹ ma n sọ pe ọkunrin ti kii ba ni ibalopọ rara tabi ni igba gbogbo yoo ni jẹjẹrẹ ni koropọn rẹ, Okoli sọ pe yatọ si ibalopọ pẹlu obinrin, awọn ọkunrin ma n da atọ loju orun, eyi ti awọn oni Gẹẹsi n pe ni 'Wet Dream'. Fun obinrin, ọ̀kan lara kudiẹ-kudiẹ to wa ninu aini ibalopọ fun igba pipẹ ni pe o le fa irora nigba to ba fẹ ẹ ni. | https://www.bbc.com/yoruba/60105041 |
5sports
| Diego Maradona: Báyìí ni àgbàọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù Diego Maradona ṣe wọ káà ilẹ̀ lọ lólú ìlú Argentina | Ba a ku laa dere eeyan o sunwọn laaye. Agbaọjẹ agbabọọlu Argentina yẹlẹ ri, Diego Maradona ti wọ kaa ilẹ lọlẹyin to papoda lẹni ọgọta ọdun. Olu ilu orilẹede Argentina, Buenos Aires ni wọn sin Maradona si nibi ti ọpọ ti pejọ lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun elege ara to filẹ ṣaṣọ bora. Awọn ẹbi ti ko ju mẹrinlelogun lọ pẹlu awọn ọrẹ rẹ lo wa nibi ayẹyẹ isinku Maradona l'Ọjọbọ. Amọ, ọgọọrọ eeyan lo lanfaani lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un, ọpọ lo n sunkun, nigba ti awọn mii n ṣe sadakanta lẹgbẹ posi Maradona. Iku Maradona ti mu ki gbogbo eeyan lagbaaye papaa julọ awọn ololufẹ ere bọọlu ṣe idaro ẹni 're to lọ papaa julọ nilẹ abinibi rẹ, Argentina. Koda asia orilẹede Argentina ati jẹsi rẹ pẹlu nọmba ''10'' ti o maa n wọ wa lori posi Maradona fun awọn eeyan lati ri lolu ileeṣẹ ijọba ilẹ naa. Awọn agbofinro tiẹ ni ikọlu pẹlu awọn oludaro to n gbiyanju lati suu mọ olu ileeṣẹ ijọba nibi ti wọn gbe posi Maradona si. Iroyin kan tiẹ tun sọ pe awọn ọlọpaa yin tajutaju lati dari awọn ero nibi eto isinku naa. Ọkọ igboku si lo gbe posi Maradona lo si ilẹ isinku si Bella Vista ni bi ti o ti sun. Ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn Diego Maradona ìlúmọọká agbábọ́ọ̀lù rèé kó tó dágbére f'áyé Ohun mẹta ti ẹda kan ko mọ laye ti a wa yii ni pe ko si ẹni to mọ iru iku ti yoo pa a. Ekeji ni pe ko si ẹni to mọ igba ati akoko ti ọlọjọ yoo de ati pe ko si ẹda ẹni to mọ ibi ti o maa ku sii. Awọn ọmọ orilẹede Argentina ati gbogbo agbaye si n ṣe idaro gbajugbaja agbabọọlu elege ara, Diego Maradona ti filẹ ṣaṣọ bora lẹni ọgọta ọdun l'Ọjọru. Amọ kinni ọrọ ti ogbontarigi agbabọọlu naa sọ kẹyin ki o to jẹ Eleduwa ni pe. Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ lati orilẹede Argentina, Maradona sọ fun ọmọkunrin to wa pẹlu rẹ ni ede ilu rẹ pe ''Me siento mal,'' eyi to tumọ si ''o n rẹ mi.'' Ara Maradona ko le daadaa nigba to lọ jẹ ounjẹ aarọ Ọjọru, o ṣaroye pe otutu n mu oun. Lẹyin naa lo sọ fun ẹbi rẹ kan pe o n rẹ oun ki o to pada sori ibusun rẹ ki ẹlẹmi to gba a. Ayẹwo oku fihan pe arun ikọlu ọkan to ṣekupa Maradona lẹyin ọsẹ meji to ṣe iṣẹ abẹ ọpọlọ lati ko ẹjọ to da sii lọpọlọ kuro. Ẹwẹ, aarẹ orilẹede Argentina, Alberto Fernandez ti kede ọjọ mẹta lati kẹdun Maradona. Diego Maradona ìlúmọọká agbábọ́ọ̀lù dágbére f'áyé Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo sọ pe gbajugbaja agbabọọlu ni ọmọ Argentina Diego Maradona ti dagbere faye. Ikede yi ta ri ka loju opo awọn ileesẹ iroyin sọ pe o faye silẹ laipẹ ọjọ ti o ṣe isẹ abẹ ọpọlọ. Ẹni ọgọta aọdun ni Maradona ko to fi aye silẹ. Maradona je okan lara agbabọọlu to lamilaka julọ lagbaye. O tun jẹ agbabọọlu ọmọ Argentina tó gbà ife ẹyẹ agbaye gẹgẹ bi Balogun ikọ ọmọ agbabọọlu Argentina. Ọpọ ni yoo maa ṣe iranti Maradona fun goolu rẹ to fọwọ jẹ ninu idije agbaye eyi ti Argentina fi gbewuro soju ilẹ Gẹẹsi ni Mexico 86. Tolori tẹlẹmu ni ko ni gbagbe ilumọọka agbabọọlu elege ara yi to ṣe pe o ko ipa ribi ribi ninu ere bọọlu lagbaye. Nigba aye rẹ, o gba bọọlu fún ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona àti Napoli ó si gba ife ẹyẹ pelu lẹẹmeji ni Serie A. | Diego Maradona: Báyìí ni àgbàọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù Diego Maradona ṣe wọ káà ilẹ̀ lọ lólú ìlú Argentina Ba a ku laa dere eeyan o sunwọn laaye. Agbaọjẹ agbabọọlu Argentina yẹlẹ ri, Diego Maradona ti wọ kaa ilẹ lọlẹyin to papoda lẹni ọgọta ọdun. Olu ilu orilẹede Argentina, Buenos Aires ni wọn sin Maradona si nibi ti ọpọ ti pejọ lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun elege ara to filẹ ṣaṣọ bora. Awọn ẹbi ti ko ju mẹrinlelogun lọ pẹlu awọn ọrẹ rẹ lo wa nibi ayẹyẹ isinku Maradona l'Ọjọbọ. Amọ, ọgọọrọ eeyan lo lanfaani lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un, ọpọ lo n sunkun, nigba ti awọn mii n ṣe sadakanta lẹgbẹ posi Maradona. Iku Maradona ti mu ki gbogbo eeyan lagbaaye papaa julọ awọn ololufẹ ere bọọlu ṣe idaro ẹni 're to lọ papaa julọ nilẹ abinibi rẹ, Argentina. Koda asia orilẹede Argentina ati jẹsi rẹ pẹlu nọmba ''10'' ti o maa n wọ wa lori posi Maradona fun awọn eeyan lati ri lolu ileeṣẹ ijọba ilẹ naa. Awọn agbofinro tiẹ ni ikọlu pẹlu awọn oludaro to n gbiyanju lati suu mọ olu ileeṣẹ ijọba nibi ti wọn gbe posi Maradona si. Iroyin kan tiẹ tun sọ pe awọn ọlọpaa yin tajutaju lati dari awọn ero nibi eto isinku naa. Ọkọ igboku si lo gbe posi Maradona lo si ilẹ isinku si Bella Vista ni bi ti o ti sun. Ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn Diego Maradona ìlúmọọká agbábọ́ọ̀lù rèé kó tó dágbére f'áyé Ohun mẹta ti ẹda kan ko mọ laye ti a wa yii ni pe ko si ẹni to mọ iru iku ti yoo pa a. Ekeji ni pe ko si ẹni to mọ igba ati akoko ti ọlọjọ yoo de ati pe ko si ẹda ẹni to mọ ibi ti o maa ku sii. Awọn ọmọ orilẹede Argentina ati gbogbo agbaye si n ṣe idaro gbajugbaja agbabọọlu elege ara, Diego Maradona ti filẹ ṣaṣọ bora lẹni ọgọta ọdun l'Ọjọru. Amọ kinni ọrọ ti ogbontarigi agbabọọlu naa sọ kẹyin ki o to jẹ Eleduwa ni pe. Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ lati orilẹede Argentina, Maradona sọ fun ọmọkunrin to wa pẹlu rẹ ni ede ilu rẹ pe ''Me siento mal,'' eyi to tumọ si ''o n rẹ mi.'' Ara Maradona ko le daadaa nigba to lọ jẹ ounjẹ aarọ Ọjọru, o ṣaroye pe otutu n mu oun. Lẹyin naa lo sọ fun ẹbi rẹ kan pe o n rẹ oun ki o to pada sori ibusun rẹ ki ẹlẹmi to gba a. Ayẹwo oku fihan pe arun ikọlu ọkan to ṣekupa Maradona lẹyin ọsẹ meji to ṣe iṣẹ abẹ ọpọlọ lati ko ẹjọ to da sii lọpọlọ kuro. Ẹwẹ, aarẹ orilẹede Argentina, Alberto Fernandez ti kede ọjọ mẹta lati kẹdun Maradona. Diego Maradona ìlúmọọká agbábọ́ọ̀lù dágbére f'áyé Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo sọ pe gbajugbaja agbabọọlu ni ọmọ Argentina Diego Maradona ti dagbere faye. Ikede yi ta ri ka loju opo awọn ileesẹ iroyin sọ pe o faye silẹ laipẹ ọjọ ti o ṣe isẹ abẹ ọpọlọ. Ẹni ọgọta aọdun ni Maradona ko to fi aye silẹ. Maradona je okan lara agbabọọlu to lamilaka julọ lagbaye. O tun jẹ agbabọọlu ọmọ Argentina tó gbà ife ẹyẹ agbaye gẹgẹ bi Balogun ikọ ọmọ agbabọọlu Argentina. Ọpọ ni yoo maa ṣe iranti Maradona fun goolu rẹ to fọwọ jẹ ninu idije agbaye eyi ti Argentina fi gbewuro soju ilẹ Gẹẹsi ni Mexico 86. Tolori tẹlẹmu ni ko ni gbagbe ilumọọka agbabọọlu elege ara yi to ṣe pe o ko ipa ribi ribi ninu ere bọọlu lagbaye. Nigba aye rẹ, o gba bọọlu fún ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona àti Napoli ó si gba ife ẹyẹ pelu lẹẹmeji ni Serie A. | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-55078990 |
3politics
| Kogi PDP Primaries: Wada fẹ̀yìn Dino gbálẹ̀ nínú ìbò abẹ́lé PDP fún ìpò gómìnà ní Kogi | Amoju ẹro Musa Wada la Sẹnẹtọ Dino Melaye mọ lẹ ninu ibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP fun ibo gomina ipinlẹ Kogi oṣi kọkanla. Amoju ẹrọ Wada jawe olubori ninu eto idibo ọhun pẹlu ibo aadọta le ni ẹẹdẹgbẹrin o din meji. Ọgbẹni Ibrahim Abubakar lo ṣe ipo keji pẹlu mẹwaa le ni ẹẹdẹgbẹrin. Nibayii, Wada ni yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ninu ibo gomina ti yoo waye lọjọ kẹriundinlogun oṣu kọkanla ọdun 2019. Wada yoo ta kaungbọn pẹlu Gomina Yahaya Bello to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC atawọn oludigbe ẹgbẹ oṣelu miiran ninu ibo ọhun. Àwọn èèyàn Yahaya Bello ló da ìbò abẹ́nú wa ní Kogi rú- PDP Awọn eeyan Gomina Yahaya Bello lo wa fibọn da eto ibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP niluu Lokoja ru. Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP, Kola Ọlọgbọndiyan to ba BBC Yoruba sọrọ, ṣalaye pe ayẹwo ibo lawọn n ṣe lọwọ nigba ti awọn janduku ọhun yabo gbọngan idibo naa ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn pẹrẹpẹ. Ọgbẹni Ọlọgbọdiyan ni ọpọ eeyan lo farapa nigba tawọn mii si dero ile iwosan ninu iṣẹlẹ ọhun lolu ilu ipinlẹ Kogi ti eto idibo naa ti waye. O ṣalaye siwaju si pe oun ko le sọ bi Gomina Ahmadu Fintri ipinlẹ Adamawa to jẹ alaga eto idibo abẹnu naa ṣe mo ri bọ nigba tawọn agbebọn dabọn bo lẹ. Amọ, o fikun ọrọ rẹ pe atundi ibo ko ni waye nitori eto idibo naa si n tẹsiwaju lonii, koda o sọ pe igbimọ eto idibo abẹnu yoo kede ẹni to ba bori ninu idibo abẹnu naa l'Ọjọru. O ni ohun kan to ku ni lati kede orukọ ẹni to jawe olubori ninu ibo ki wọn to ko ibọn wọ le. Ọgbẹni Ọlọgbọndiyan sọ pe ni gbogbo igba ti Gomina Bello ipinlẹ Kogi ba ti ri wi pe ẹgbẹ mii fẹ fa eeyan ka lẹ lati koju òun ninu ibo lo maa n da iru eto bẹẹ ru. Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP tun kilọ fun Gomina Yahaya Bello ati ẹgbẹ APC pe iwa jagidijagan ko le gba wọn ninu idibo gomina to n bọ ninu oṣu kọkanla. Ọlọgbọndiyan ninu atẹjade to fi sita lorukọ ẹgbẹ PDP sọ pe mimi kan ko le mi ẹgbẹ naa ohun to wu ki ẹgbẹ APC ṣe. | Kogi PDP Primaries: Wada fẹ̀yìn Dino gbálẹ̀ nínú ìbò abẹ́lé PDP fún ìpò gómìnà ní Kogi Amoju ẹro Musa Wada la Sẹnẹtọ Dino Melaye mọ lẹ ninu ibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP fun ibo gomina ipinlẹ Kogi oṣi kọkanla. Amoju ẹrọ Wada jawe olubori ninu eto idibo ọhun pẹlu ibo aadọta le ni ẹẹdẹgbẹrin o din meji. Ọgbẹni Ibrahim Abubakar lo ṣe ipo keji pẹlu mẹwaa le ni ẹẹdẹgbẹrin. Nibayii, Wada ni yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ninu ibo gomina ti yoo waye lọjọ kẹriundinlogun oṣu kọkanla ọdun 2019. Wada yoo ta kaungbọn pẹlu Gomina Yahaya Bello to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC atawọn oludigbe ẹgbẹ oṣelu miiran ninu ibo ọhun. Àwọn èèyàn Yahaya Bello ló da ìbò abẹ́nú wa ní Kogi rú- PDP Awọn eeyan Gomina Yahaya Bello lo wa fibọn da eto ibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP niluu Lokoja ru. Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP, Kola Ọlọgbọndiyan to ba BBC Yoruba sọrọ, ṣalaye pe ayẹwo ibo lawọn n ṣe lọwọ nigba ti awọn janduku ọhun yabo gbọngan idibo naa ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn pẹrẹpẹ. Ọgbẹni Ọlọgbọdiyan ni ọpọ eeyan lo farapa nigba tawọn mii si dero ile iwosan ninu iṣẹlẹ ọhun lolu ilu ipinlẹ Kogi ti eto idibo naa ti waye. O ṣalaye siwaju si pe oun ko le sọ bi Gomina Ahmadu Fintri ipinlẹ Adamawa to jẹ alaga eto idibo abẹnu naa ṣe mo ri bọ nigba tawọn agbebọn dabọn bo lẹ. Amọ, o fikun ọrọ rẹ pe atundi ibo ko ni waye nitori eto idibo naa si n tẹsiwaju lonii, koda o sọ pe igbimọ eto idibo abẹnu yoo kede ẹni to ba bori ninu idibo abẹnu naa l'Ọjọru. O ni ohun kan to ku ni lati kede orukọ ẹni to jawe olubori ninu ibo ki wọn to ko ibọn wọ le. Ọgbẹni Ọlọgbọndiyan sọ pe ni gbogbo igba ti Gomina Bello ipinlẹ Kogi ba ti ri wi pe ẹgbẹ mii fẹ fa eeyan ka lẹ lati koju òun ninu ibo lo maa n da iru eto bẹẹ ru. Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP tun kilọ fun Gomina Yahaya Bello ati ẹgbẹ APC pe iwa jagidijagan ko le gba wọn ninu idibo gomina to n bọ ninu oṣu kọkanla. Ọlọgbọndiyan ninu atẹjade to fi sita lorukọ ẹgbẹ PDP sọ pe mimi kan ko le mi ẹgbẹ naa ohun to wu ki ẹgbẹ APC ṣe. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49583650 |
2health
| Snail Slim Soap: Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú lílo ọ̀ṣẹ tí wọn fi omi ìgbín ṣe láti fọ ojú | Ara meeriri ree, a ti ri oju ologbo lori atẹ, paapaa nidi oge sise. Gẹgẹ bẹẹ se mọ pe awọn obinrin kii fi oge sise sere rara, paapaa nidi ohun ti yoo ba mu ki awọ ara wọn jọlọ, ti oju wọn yoo si gun rege. Boya eyi lo mu ki ọkunrin kan se iwadii, to si gbe esi iwadi rẹ sita nipa amulo omi ara igbin, ti yoo mu ki oju gun rege. Ọkunrin onisẹ iwadii naa, Damien Desrocher, tii se ọmọ ọdun mejidinlọgbọn lati ilẹ Faranse jẹ ara eeyan mẹta to n fi omi igbin se ọsẹ ifọju. Awọn igbin to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọta ni Damien n sin, to si tun n gbero lati pese ọsẹ omi igbin bii ẹgbẹrun mẹta lọdun yii. Nigba to n ba BBC sọrọ, Damien salaye pe awọn kii pa igbin kankan lara lasiko ti wsn ba n yọ omi ara wọn, ti awọn omi igbin naa si wulo fun iwosan. Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: O fikun pe omi ara igbin ni eroja ti wọn n pe ni Collagen ati Elastin, ti kii jẹ ki oju eeyan tete gbo. | Snail Slim Soap: Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú lílo ọ̀ṣẹ tí wọn fi omi ìgbín ṣe láti fọ ojú Ara meeriri ree, a ti ri oju ologbo lori atẹ, paapaa nidi oge sise. Gẹgẹ bẹẹ se mọ pe awọn obinrin kii fi oge sise sere rara, paapaa nidi ohun ti yoo ba mu ki awọ ara wọn jọlọ, ti oju wọn yoo si gun rege. Boya eyi lo mu ki ọkunrin kan se iwadii, to si gbe esi iwadi rẹ sita nipa amulo omi ara igbin, ti yoo mu ki oju gun rege. Ọkunrin onisẹ iwadii naa, Damien Desrocher, tii se ọmọ ọdun mejidinlọgbọn lati ilẹ Faranse jẹ ara eeyan mẹta to n fi omi igbin se ọsẹ ifọju. Awọn igbin to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọta ni Damien n sin, to si tun n gbero lati pese ọsẹ omi igbin bii ẹgbẹrun mẹta lọdun yii. Nigba to n ba BBC sọrọ, Damien salaye pe awọn kii pa igbin kankan lara lasiko ti wsn ba n yọ omi ara wọn, ti awọn omi igbin naa si wulo fun iwosan. Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: O fikun pe omi ara igbin ni eroja ti wọn n pe ni Collagen ati Elastin, ti kii jẹ ki oju eeyan tete gbo. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57373685 |
1entertainment
| Yollywood: Baba Wande, Kareem Adepoju, Jide Kosoko, Taiwo Hassan, Yinka Quadri àti Alapinni jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn àgbà òṣèré májẹ́kòbájẹ̀ àsìkò yìí | Iriri kọja ẹgbẹ abẹwu ni ọrọ awọn agba osere kọọkan jẹ. Ohunkohun ti eeyan ba yan láayo, o dara lati fi gbogbo ara ṣe e ki o le moke nibẹ. Opọ agba osere lo ti fi ara ṣiṣẹ ki iṣẹ tiata to de ibi to de duro yii, awọn miran ri re ibi agba n re nigba ti awon mii si wa lori oke eepe. Diẹ ninu awọn ọpọ osere titata to si wa laye di isinyii ni a ti ri awon ti ọpọ n pe lorukọ ere ori itage bii: Jide Kosoko, Baba Wande, Ogogo, Kura, Oga Bello ati Alapinni Oosa yatọ si awọn mii ti won tun n sise karakara. 1. Kareem Adepoju ti ọpọ mo si Baba Wande: Baba Wande bẹrẹ si ni di gbajumo leyin to se ere Ti Oluwa ni ilẹ ni ọdun 1993 nigba to kopa gege bii Oloye Otun. Lara awon ere to ti se ni Ayo ni Mo fe, Abeni, Arugba, Igbekun, Obuko Dudu, Ika Lomo Ejo, Enu Eye, Oba bi Olorun ati bẹẹ bẹẹ lọ. Oloye Karem Adepoju ti se ọpọlọpọ ere ori itage, ere sinima ati ere agbelewo. Iriri to pọ ni Oloye yii ni to si fi n kọ awon ọdọ osere isinyi. 2: Jide Kosoko: Jide Kosoko jẹ ọkan lara agba oṣere ti wọn bi ere ṣiṣe mọ lati ibẹrẹ. Ojọ kejila, osu kinni ọdun 1954 ni a bii sile ọla nibi to ti kawe to si bẹrẹ ere itage sise lati ọmọ kekere ni Ebutte Metta ni agbegbe to dagba si ni ilu Eko. O kawe gboye ninu ẹkọ 'Business Administration' lati ile ẹkọ Yaba College of Education ni ipinlẹ Eko. Leyin naa lo lọ kọsẹ ere itage sii ni Fasiti Olabisi Onabanjo ni Ago Iwoye. Jide Kosoko naa bẹrẹ ere tiata pẹlu awọn alarinjo Ifelodun Traveling Theatre Group. Diẹ lara ere ti Jide Kosoko ti kopa ni ede Yoruba ni: 'Eje Adegbenro', 'Durodola', 'Koseegbe', 'Oro Nla' nigba ti awọn mii lede oyinbo ni 'King of Boys', 'The Bling Lagosian', 'Reunion', ati awon mii. Awọn ọmọ bibi rẹ obinrin meji naa ni wọn ti darapọ mọ baba wọn lẹnu iṣẹ ere itage. Awon naa ni Sola ati Bidemi Kosoko. 3: Taiwo Hassan- Ogogo Kulodo Agba Osere yii jẹ ọkan lara awọn agba oṣere ti aye n fẹ lasiko yii. Opọ maa n yin fun ọgbọn atinuda to fi maa n gbe ero rẹ kalẹ ninu ipa ti wọn ba fun Ogogo ṣe. Wọn maa n sọ pe kii fẹ ko ipa ti yoo ti maa tẹnubọ osere binrin mii lẹnu rara. Ojọ kọkanlelọgbọn, osu kẹwaa, ọdun 1959 ni wọn bi Ogogo ni ilu Ilaro. O lọ sile ẹkọ Christ Church School ati Yaba Technical College ninu iṣẹ atun ọkọ ṣe ti won pe ni 'automobile mechanic'. Ogogo ba ileeṣẹ Water Corporation sise fun ọdun mẹtala lati 1981 si 1994 ko to darapọ mọ awọn oṣere. Diẹ lara awọn ere ti Ogogo ti kopa ni 'Bolode O'ku', 'Apadi', 'Owo Blow', 'Obinrin So Wa Nu Taiwo Hassan fẹ iyawo meji o si sabiyamọ ọmọ mẹrin. 4. Adebayo Salami- Oga Bello: Agba ọjẹ ọṣere ni Adebayo Salami lati ipinle Kwara. A bii ni ọjọ kẹsan an, oṣu karun un, ọdun 1952 nipinle Eko. Lati kekere ni o ti bẹrẹ ere itage alarinjo nigba to darapọ mọ Young concert Party ti oloogbe Ojo duro Ladiipo. To pada yi oruko pada si Awada kerikeri nigba ti Oga Bello di adari won leyin iku Ojo Ladiipo. Ajani Ogun ni fiimu akọkọ to gbe Oga Bello sita ni eyi ti oun naa geb Ogun Ajaye sita. O ti se ọpọlọpọ fiimu to si ti kopa ninu ogunlọgọ fiimu. Awọn ọmọ rẹ naa si ti darapọ mọ ọ ninu iṣẹ ere itage bayii. Lara wọn la ti ri: Femi Adebayo, Tope Adebayo ati bẹẹ bẹẹ lọ. 5. Yinka Quadri: Yinka Quadri ti ọpọ n pe ni Kura jẹ agba oṣere. O jẹ Oludari ere ati olootu ere sinima. A bi Yinka Quadri ni ọjọ kẹfa, osu kẹsan an, ọdun 1959 ni agbegbe Lagos Island nipinle Eko. O jẹ ọmọ ilu Oro nipinle Kwara. Oun naa ni Agbaakin ilẹ̀ Oro ni ipinle Kwara. O lọ sile ẹkọ St Catholic School ni Idumagbo ati Christ High School ni Ebute Elefun nipinle Eko. Odun 1976 ni Yinka Qudri bẹrẹ ere sise pẹlu awon ọrẹ rẹ kan bii Taiwo Olayinka eyi ti wọn pe orukọ rẹ ni Afopina Theatre Group. Yinka Qudri kopa ninu ere olọsọọsẹ ati awọn ere onise mii bii Abulesowo, Bolode O ku, 'Apadi', 'Egbinrin Ote', 'Kutupu' ati béé béé lọ. Yinak fẹ iyawo o si bimọ ati ọmọ ọmọ pẹlu awọn ọmọ ori itage to pọ. 6. Ganiu Nafiu: Alapinni: Ọpọ nkan nipa agbaọjẹ oṣere ni Ganiu Nafiu ti ọpọ mọ si Alapinni Oosa. Ko si ẹni to le fidi ọjọ ori rẹ mulẹ nipato ṣugbon wọn gba pe o ti le ni ọgọrin ọdun. O jẹ ẹlẹsin musulumi ṣugbon o ni imọ kikun nipa ẹsin abalaye. Opo ololufẹ Alapinni Oosa ni wọn maa n gbadun ohun rẹ to yatọ. O ti le logoji ọdun sẹyin to ti n ṣe ere itage kaakii. Opo igba ni Rafiu Ganiyu maa n ṣe babalawo ninu ere Yoruba. Saaju ko to maa ṣere lo ti kọkọ n ṣe awada kiri adugbo pẹlu awọn ọrẹ rẹ kan. Lẹyin iku ọkan ninu wọn lo gba ile keu lọ ko to da ẹgbẹ tirẹ silẹ ni 1979. O pada ba awọn agba ọjẹ oṣere bii Akin Ogungbe, Ray Eyiwumi ati awọn mii ṣere. Ni Ipari, Awọn agba ọjẹ osere yii wa lara awọn to n mu itẹsiwaju ba agbo ere oniṣe Yoruba. Ki ogo Yoruba maa tẹsiwaju lo wu awọn ololufẹ ede naa ninu iṣẹ akada ati lagbo idanilaraya. | Yollywood: Baba Wande, Kareem Adepoju, Jide Kosoko, Taiwo Hassan, Yinka Quadri àti Alapinni jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn àgbà òṣèré májẹ́kòbájẹ̀ àsìkò yìí Iriri kọja ẹgbẹ abẹwu ni ọrọ awọn agba osere kọọkan jẹ. Ohunkohun ti eeyan ba yan láayo, o dara lati fi gbogbo ara ṣe e ki o le moke nibẹ. Opọ agba osere lo ti fi ara ṣiṣẹ ki iṣẹ tiata to de ibi to de duro yii, awọn miran ri re ibi agba n re nigba ti awon mii si wa lori oke eepe. Diẹ ninu awọn ọpọ osere titata to si wa laye di isinyii ni a ti ri awon ti ọpọ n pe lorukọ ere ori itage bii: Jide Kosoko, Baba Wande, Ogogo, Kura, Oga Bello ati Alapinni Oosa yatọ si awọn mii ti won tun n sise karakara. 1. Kareem Adepoju ti ọpọ mo si Baba Wande: Baba Wande bẹrẹ si ni di gbajumo leyin to se ere Ti Oluwa ni ilẹ ni ọdun 1993 nigba to kopa gege bii Oloye Otun. Lara awon ere to ti se ni Ayo ni Mo fe, Abeni, Arugba, Igbekun, Obuko Dudu, Ika Lomo Ejo, Enu Eye, Oba bi Olorun ati bẹẹ bẹẹ lọ. Oloye Karem Adepoju ti se ọpọlọpọ ere ori itage, ere sinima ati ere agbelewo. Iriri to pọ ni Oloye yii ni to si fi n kọ awon ọdọ osere isinyi. 2: Jide Kosoko: Jide Kosoko jẹ ọkan lara agba oṣere ti wọn bi ere ṣiṣe mọ lati ibẹrẹ. Ojọ kejila, osu kinni ọdun 1954 ni a bii sile ọla nibi to ti kawe to si bẹrẹ ere itage sise lati ọmọ kekere ni Ebutte Metta ni agbegbe to dagba si ni ilu Eko. O kawe gboye ninu ẹkọ 'Business Administration' lati ile ẹkọ Yaba College of Education ni ipinlẹ Eko. Leyin naa lo lọ kọsẹ ere itage sii ni Fasiti Olabisi Onabanjo ni Ago Iwoye. Jide Kosoko naa bẹrẹ ere tiata pẹlu awọn alarinjo Ifelodun Traveling Theatre Group. Diẹ lara ere ti Jide Kosoko ti kopa ni ede Yoruba ni: 'Eje Adegbenro', 'Durodola', 'Koseegbe', 'Oro Nla' nigba ti awọn mii lede oyinbo ni 'King of Boys', 'The Bling Lagosian', 'Reunion', ati awon mii. Awọn ọmọ bibi rẹ obinrin meji naa ni wọn ti darapọ mọ baba wọn lẹnu iṣẹ ere itage. Awon naa ni Sola ati Bidemi Kosoko. 3: Taiwo Hassan- Ogogo Kulodo Agba Osere yii jẹ ọkan lara awọn agba oṣere ti aye n fẹ lasiko yii. Opọ maa n yin fun ọgbọn atinuda to fi maa n gbe ero rẹ kalẹ ninu ipa ti wọn ba fun Ogogo ṣe. Wọn maa n sọ pe kii fẹ ko ipa ti yoo ti maa tẹnubọ osere binrin mii lẹnu rara. Ojọ kọkanlelọgbọn, osu kẹwaa, ọdun 1959 ni wọn bi Ogogo ni ilu Ilaro. O lọ sile ẹkọ Christ Church School ati Yaba Technical College ninu iṣẹ atun ọkọ ṣe ti won pe ni 'automobile mechanic'. Ogogo ba ileeṣẹ Water Corporation sise fun ọdun mẹtala lati 1981 si 1994 ko to darapọ mọ awọn oṣere. Diẹ lara awọn ere ti Ogogo ti kopa ni 'Bolode O'ku', 'Apadi', 'Owo Blow', 'Obinrin So Wa Nu Taiwo Hassan fẹ iyawo meji o si sabiyamọ ọmọ mẹrin. 4. Adebayo Salami- Oga Bello: Agba ọjẹ ọṣere ni Adebayo Salami lati ipinle Kwara. A bii ni ọjọ kẹsan an, oṣu karun un, ọdun 1952 nipinle Eko. Lati kekere ni o ti bẹrẹ ere itage alarinjo nigba to darapọ mọ Young concert Party ti oloogbe Ojo duro Ladiipo. To pada yi oruko pada si Awada kerikeri nigba ti Oga Bello di adari won leyin iku Ojo Ladiipo. Ajani Ogun ni fiimu akọkọ to gbe Oga Bello sita ni eyi ti oun naa geb Ogun Ajaye sita. O ti se ọpọlọpọ fiimu to si ti kopa ninu ogunlọgọ fiimu. Awọn ọmọ rẹ naa si ti darapọ mọ ọ ninu iṣẹ ere itage bayii. Lara wọn la ti ri: Femi Adebayo, Tope Adebayo ati bẹẹ bẹẹ lọ. 5. Yinka Quadri: Yinka Quadri ti ọpọ n pe ni Kura jẹ agba oṣere. O jẹ Oludari ere ati olootu ere sinima. A bi Yinka Quadri ni ọjọ kẹfa, osu kẹsan an, ọdun 1959 ni agbegbe Lagos Island nipinle Eko. O jẹ ọmọ ilu Oro nipinle Kwara. Oun naa ni Agbaakin ilẹ̀ Oro ni ipinle Kwara. O lọ sile ẹkọ St Catholic School ni Idumagbo ati Christ High School ni Ebute Elefun nipinle Eko. Odun 1976 ni Yinka Qudri bẹrẹ ere sise pẹlu awon ọrẹ rẹ kan bii Taiwo Olayinka eyi ti wọn pe orukọ rẹ ni Afopina Theatre Group. Yinka Qudri kopa ninu ere olọsọọsẹ ati awọn ere onise mii bii Abulesowo, Bolode O ku, 'Apadi', 'Egbinrin Ote', 'Kutupu' ati béé béé lọ. Yinak fẹ iyawo o si bimọ ati ọmọ ọmọ pẹlu awọn ọmọ ori itage to pọ. 6. Ganiu Nafiu: Alapinni: Ọpọ nkan nipa agbaọjẹ oṣere ni Ganiu Nafiu ti ọpọ mọ si Alapinni Oosa. Ko si ẹni to le fidi ọjọ ori rẹ mulẹ nipato ṣugbon wọn gba pe o ti le ni ọgọrin ọdun. O jẹ ẹlẹsin musulumi ṣugbon o ni imọ kikun nipa ẹsin abalaye. Opo ololufẹ Alapinni Oosa ni wọn maa n gbadun ohun rẹ to yatọ. O ti le logoji ọdun sẹyin to ti n ṣe ere itage kaakii. Opo igba ni Rafiu Ganiyu maa n ṣe babalawo ninu ere Yoruba. Saaju ko to maa ṣere lo ti kọkọ n ṣe awada kiri adugbo pẹlu awọn ọrẹ rẹ kan. Lẹyin iku ọkan ninu wọn lo gba ile keu lọ ko to da ẹgbẹ tirẹ silẹ ni 1979. O pada ba awọn agba ọjẹ oṣere bii Akin Ogungbe, Ray Eyiwumi ati awọn mii ṣere. Ni Ipari, Awọn agba ọjẹ osere yii wa lara awọn to n mu itẹsiwaju ba agbo ere oniṣe Yoruba. Ki ogo Yoruba maa tẹsiwaju lo wu awọn ololufẹ ede naa ninu iṣẹ akada ati lagbo idanilaraya. | https://www.bbc.com/yoruba/62648794 |
1entertainment
| Dino Melaye vs Iyabo Ojo: Sẹ́nétọ̀ ní lórí irọ́ ní ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí wọn ló wà láàrin òun àtàwọn òṣèré tíátà | Laipẹ yii ni fidio kan gbode lori ayelujara, ninu eyi ti ohun gbajumọ oṣere tiata ni, Iyabọ Ojo ti n jade bi eyi to wa lori ipe ago, to si n fi gbajumọ Sẹnetọ ati ọmọ jayejaye nni, Dino Melaye ṣepe. Iyabọ Ojo n sọ ninu fọnran naa pe, Sẹnetọ Melaye n parọ fun awọn ọmọbinrin miran pe ko si ajọṣepọ kankan laarin oun pẹlu rẹ, nigba to si jẹ wi pe adehun ifẹ n bẹ laarin awọn. Bakan naa lo fi ẹsun kan Dino Melaye ninu fọnran ohun naa pe oloselu naa n sẹ nipa ajọsepọ awọ, fun awọn olulufẹ tuntun to sẹsẹ ni, to si darukọ Omoburty. Amọṣa, gbajumọ ọmọ jayejaye naa, Sẹnetọ Dino Melaye ti fesi pe ko si ajọṣepọ ifẹ kankan laarin oun ati Iyabọ Ojo tabi Biọdun Okeowo, ti ọpọ mọ si Omoborty. Awọn oju opo ayelujara kan ti kọkọ gbe sita ṣaaju pe Dino Melaye ati Iyabọ Ojo jijọ n ṣe wọlewọde tẹlẹ, ki oṣere ẹgbẹ rẹ, Ọmọborty to jaa gba mọọ lọwọ. Bakan naa ni iroyin sọ pe osere tiata kan Olabisi ọmọ Logbalogba, ti ọmọ kan fun Sẹnetọ Dino Melaye amọ ti onitọun kọ pe ko ri bẹẹ. Sẹnetọ Melaye ni "Lori irọ" ni gbogbo iroyin naa pẹlu fọnrọn ohun ti Iyabọ Ojo ti n sọ pe irọ ni Dino n pa kiri fawọn obinrin to ba kọ ẹnu ifẹ si pe oun Iyabọ lo n le Dino kiri lati fẹ oun. "O ga oooo. Dino fẹ fẹ A sile, Dino fun B loyun, Dino n ṣe aayan ifẹ pẹlu C, gbogbo rẹ lori irọ ni....haba!!!! Ẹ maa daamu jina, maa fẹyawo laipẹ, koboko ni yoo si fi le gbogbo yin danu. Ẹyin alainiṣẹ gbogbo." Ọrọ bi edeaiyede kii se lori Dino Melaye. Fun ọdun mẹwaa ni oun pẹlu Tokunbọ Melaye fi fẹra ni lọkọlaya, ki tirela to gba aarin wọn kọja lẹyin ọmọ mẹta. | Dino Melaye vs Iyabo Ojo: Sẹ́nétọ̀ ní lórí irọ́ ní ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí wọn ló wà láàrin òun àtàwọn òṣèré tíátà Laipẹ yii ni fidio kan gbode lori ayelujara, ninu eyi ti ohun gbajumọ oṣere tiata ni, Iyabọ Ojo ti n jade bi eyi to wa lori ipe ago, to si n fi gbajumọ Sẹnetọ ati ọmọ jayejaye nni, Dino Melaye ṣepe. Iyabọ Ojo n sọ ninu fọnran naa pe, Sẹnetọ Melaye n parọ fun awọn ọmọbinrin miran pe ko si ajọṣepọ kankan laarin oun pẹlu rẹ, nigba to si jẹ wi pe adehun ifẹ n bẹ laarin awọn. Bakan naa lo fi ẹsun kan Dino Melaye ninu fọnran ohun naa pe oloselu naa n sẹ nipa ajọsepọ awọ, fun awọn olulufẹ tuntun to sẹsẹ ni, to si darukọ Omoburty. Amọṣa, gbajumọ ọmọ jayejaye naa, Sẹnetọ Dino Melaye ti fesi pe ko si ajọṣepọ ifẹ kankan laarin oun ati Iyabọ Ojo tabi Biọdun Okeowo, ti ọpọ mọ si Omoborty. Awọn oju opo ayelujara kan ti kọkọ gbe sita ṣaaju pe Dino Melaye ati Iyabọ Ojo jijọ n ṣe wọlewọde tẹlẹ, ki oṣere ẹgbẹ rẹ, Ọmọborty to jaa gba mọọ lọwọ. Bakan naa ni iroyin sọ pe osere tiata kan Olabisi ọmọ Logbalogba, ti ọmọ kan fun Sẹnetọ Dino Melaye amọ ti onitọun kọ pe ko ri bẹẹ. Sẹnetọ Melaye ni "Lori irọ" ni gbogbo iroyin naa pẹlu fọnrọn ohun ti Iyabọ Ojo ti n sọ pe irọ ni Dino n pa kiri fawọn obinrin to ba kọ ẹnu ifẹ si pe oun Iyabọ lo n le Dino kiri lati fẹ oun. "O ga oooo. Dino fẹ fẹ A sile, Dino fun B loyun, Dino n ṣe aayan ifẹ pẹlu C, gbogbo rẹ lori irọ ni....haba!!!! Ẹ maa daamu jina, maa fẹyawo laipẹ, koboko ni yoo si fi le gbogbo yin danu. Ẹyin alainiṣẹ gbogbo." Ọrọ bi edeaiyede kii se lori Dino Melaye. Fun ọdun mẹwaa ni oun pẹlu Tokunbọ Melaye fi fẹra ni lọkọlaya, ki tirela to gba aarin wọn kọja lẹyin ọmọ mẹta. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57628945 |
1entertainment
| Biola Adebayo: Oríṣiríṣi ọjà ni mo kiri ní kékeré, síbẹ̀ mí ò rí owó wọ Fáṣítì | Yoruba bọ, wọn ni oju kii pọ́n iṣin ko ma là, bi ẹkun si pẹ titi di alẹ kan, ayọ n bọ ni owurọ. Bẹẹ gan-an ni ọrọ ri fun gbajugbaja oṣerebinrin, Biola Adebayo nigba to n seranti ọpọ ipenija to la kọja, ko to jẹ eeyan nile aye. Osere naa to ranti igbe aye rẹ àtẹ̀yìnwá gẹgẹ bi ọmọ atẹrọ̀fọ̀ dide ni orisirisi nkan ni oun kiri bii ọja lasiko ijagudu lati se rere nile aye. Aworan kan ti Biola fi si ori ayelujara Instagram rẹ, lo mu ko ranti awọn asiko ti nkan nira fun nigba ewe rẹ. Ninu aworan naa, to ya nibi kan to ti n ṣe eré ti a o ti i mọ orúkọ rẹ, ni Biola ti n kiri búrẹ́dì. O ni "aworan yii mu mi ranti igbe aye mi ni ibẹrẹ pẹpẹ. Oriṣiriṣi nkan ni mo kiri gẹgẹ bi ọdọmọbinrin, sugbọn búrẹ́dì tita ni awọn eeyan fi mọ òun. O ni oun kiri burẹdi naa titi di igba ti oun di ọlọmọge ni, to si gba oun to ọdún meje, ki oun to wọ fasiti. Ko tan sibẹ o, arẹwà oṣerebinrin naa to ti lami-laaka ninu iṣẹ sinima ṣíṣe sọ pe ẹẹmẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni oun ni anfaani lati kekọọ ni fasiti, sugbọn ìṣòro aisi owo ja oun kulẹ. Biola Adebayo to dupẹ lọwọ Ọlọ́run fun ibi ti igbeaye rẹ duro de bayii sọ pe kii ṣe iwe ẹ̀rí akọkọ nikan ni oun ni, o ni oun tun ti gba iwe ẹri 'masters' keji. "Asiko naa kii ṣe nkan to rọrùn rara, àmọ́ mi o ti itori rẹ má nifẹ Ọlọ́run, bẹ ẹ ni mo si ni ireti. Ki n ma parọ, Ọlọ́run dára si mi lọpọlọpọ." O fikun ọrọ rẹ pe, lootọ òun ko ti i de ipele to wu oun, àmọ́ oun ko si ni ipele ti oun wa tẹlẹ mọ. Biola sọ pe gbogbo ẹpisteli ọrọ ti oun kọ waye lati le ṣe iwuri fun awọn eeyan pe, ki wọn o ma ṣe sọ ireti nu. " Ohunkóhun to wu ki o ma a la kọjá, ma sọ ireti nu lori ilepa rẹ. O ni idi ti o fi n la asiko naa kọjá. "Ìwọ ṣa ma a gbadura, fi Ọlọ́run ṣáájú, ja fafa, tẹra mọ isẹ rẹ, ki o si ni afojusun. Imọlẹ rẹ yoo tàn laipẹ. | Biola Adebayo: Oríṣiríṣi ọjà ni mo kiri ní kékeré, síbẹ̀ mí ò rí owó wọ Fáṣítì Yoruba bọ, wọn ni oju kii pọ́n iṣin ko ma là, bi ẹkun si pẹ titi di alẹ kan, ayọ n bọ ni owurọ. Bẹẹ gan-an ni ọrọ ri fun gbajugbaja oṣerebinrin, Biola Adebayo nigba to n seranti ọpọ ipenija to la kọja, ko to jẹ eeyan nile aye. Osere naa to ranti igbe aye rẹ àtẹ̀yìnwá gẹgẹ bi ọmọ atẹrọ̀fọ̀ dide ni orisirisi nkan ni oun kiri bii ọja lasiko ijagudu lati se rere nile aye. Aworan kan ti Biola fi si ori ayelujara Instagram rẹ, lo mu ko ranti awọn asiko ti nkan nira fun nigba ewe rẹ. Ninu aworan naa, to ya nibi kan to ti n ṣe eré ti a o ti i mọ orúkọ rẹ, ni Biola ti n kiri búrẹ́dì. O ni "aworan yii mu mi ranti igbe aye mi ni ibẹrẹ pẹpẹ. Oriṣiriṣi nkan ni mo kiri gẹgẹ bi ọdọmọbinrin, sugbọn búrẹ́dì tita ni awọn eeyan fi mọ òun. O ni oun kiri burẹdi naa titi di igba ti oun di ọlọmọge ni, to si gba oun to ọdún meje, ki oun to wọ fasiti. Ko tan sibẹ o, arẹwà oṣerebinrin naa to ti lami-laaka ninu iṣẹ sinima ṣíṣe sọ pe ẹẹmẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni oun ni anfaani lati kekọọ ni fasiti, sugbọn ìṣòro aisi owo ja oun kulẹ. Biola Adebayo to dupẹ lọwọ Ọlọ́run fun ibi ti igbeaye rẹ duro de bayii sọ pe kii ṣe iwe ẹ̀rí akọkọ nikan ni oun ni, o ni oun tun ti gba iwe ẹri 'masters' keji. "Asiko naa kii ṣe nkan to rọrùn rara, àmọ́ mi o ti itori rẹ má nifẹ Ọlọ́run, bẹ ẹ ni mo si ni ireti. Ki n ma parọ, Ọlọ́run dára si mi lọpọlọpọ." O fikun ọrọ rẹ pe, lootọ òun ko ti i de ipele to wu oun, àmọ́ oun ko si ni ipele ti oun wa tẹlẹ mọ. Biola sọ pe gbogbo ẹpisteli ọrọ ti oun kọ waye lati le ṣe iwuri fun awọn eeyan pe, ki wọn o ma ṣe sọ ireti nu. " Ohunkóhun to wu ki o ma a la kọjá, ma sọ ireti nu lori ilepa rẹ. O ni idi ti o fi n la asiko naa kọjá. "Ìwọ ṣa ma a gbadura, fi Ọlọ́run ṣáájú, ja fafa, tẹra mọ isẹ rẹ, ki o si ni afojusun. Imọlẹ rẹ yoo tàn laipẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-56746420 |
2health
| Àwọn oníṣòwò èròjà ìbóra ti rógo torí àrùn jẹjẹrẹ tó di méjì kọ́bọ̀ – NAFDAC | Ileesẹ to wa fun amojuto oogun, ounjẹ ati ohun mimu nilẹ wa, NAFDAC ti ke gbajare pe arun jẹjẹrẹ ti di tọrọ fọn kale lorilẹede yii. Nafdac wa di ẹbi isẹlẹ naa ru awọn olookowo to n pese ipara to n bo ara fawọn aralu lọna to lodi sofin. Ajọ naa ni ọpọ eroja majele fun agọ ara lawọn onisowo ibora naa n po papọ, eyi to le se ijamba fun awọ ara lode ati ninu. Oludari agba fajọ Nafdac, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye lo ke gbajare bẹẹ lasiko ifikunlukun ọlọjọ meji to waye nilu Eko. O ni asa ara bibo yii ti wa di gbajumọ laarin awọn ọkunrin ati obinrin ni Naijira, to si ti di tọrọ fọn kale. Adeyeye, ẹni to gbarata lori bawọn asaloge se n lo majele oloro fawọn onibara wọn lati fi bora tun salaye pe, awọn eroja yii ni wọn n ta lori ayelujara lowo gege. Bakan naa lo ni awọn onisowo to n polowo iku tantantan kiri ayelujara ọhun, tun maa n lẹdi apo pọ pẹlu awọn dokita onisegun oyinbo lati gun awọn to fẹ bora ni abẹrẹ. Adeyeye ni lara irufẹ abẹrẹ bẹẹ́ ni wọn lo ni eroja Vitamin C ati Glutathione ninu, eyi tawọn alaimọkan onibara yoo gba lati fi bo ara. Ọga agba fun Nafdac wa sisọ loju rẹ pe ọpọ eroja to ni majele ninu, ti wọn fi n po ọsẹ ati ipara ibora naa papọ, ni wọn n ko wọle lati oke okun. “Awọn eroja bii Kojic Acid ati Hydroquinone, ti odiwọn wọn kọja eyi to yẹ ko wọnu agọ ara, ni wọn ko fi orukọ wọn silẹ lọdọ ijọba, ti wọn si n ko wọle lati oke okun. Idi ree ti arun jẹjẹrẹ se di tọrọ fọn kale ni Naijiria nitori awọn majele yii lo n se okunfa rẹ ninu ara, tijọba si ti fofin de eroja Mercury fun ilo awọn asaraloge Bakan naa, ni awọn eroja ibora oni majele yii maa n se okunfa aisan Kidinrin ati ẹdọ fooro nitori pe o maa n gbogun ti wọn ninu agọ ara ni.’ O wa yan pe ara ti awọn eeyan ba bo loni lee se okunfa arun jẹjẹrẹ lọjọ ọla. O wa fi ewe ọmọ mọ awọn onisowo iku yii leti pe ki wọn jawọ ninu owo ti ko ni laada ọhun nitori ẹni ti ọwọ Nafdac ba tẹ ninu wọn, yoo foju bale ẹjọ, ti yoo si fi ẹwọn jura. “O nira fun Nafdac lati gba awọn olookowo ibora mu tori wọn kii patẹ rẹ” O wa gbarata pe o nira fun ajọ Nafdac lati tete gba awọn apanimayọda onisowo eroja ibora naa mu nitori kiamọsa ni wọn maa n pese eroja naa, ti wọn yoo si ta fun onibara loju ẹsẹ. O ni ọpọ wọn ni kii patẹ awọn eroja yii sori igba wọn, ki ọwọ awọn osisẹ Nafdac ma baa tẹ wọn. Adeyeye ni se ni awọn eeyan to n ko awọn eroja ti wọn n po papọ lati fi bo ara yi wọle lati oke okun, maa n gbe pamọ labẹ ilana Global Lisitng, gbe kọja lara Nafdac. Ọga agba fajọ Nafdac wa fi ọwọ gbaya pe ajọ naa ti n gbe igbesẹ lati fi awọn eeyan kan jofin lori iwa yii, ti ọwọ yoo si tẹ wọn laipẹ. | Àwọn oníṣòwò èròjà ìbóra ti rógo torí àrùn jẹjẹrẹ tó di méjì kọ́bọ̀ – NAFDAC Ileesẹ to wa fun amojuto oogun, ounjẹ ati ohun mimu nilẹ wa, NAFDAC ti ke gbajare pe arun jẹjẹrẹ ti di tọrọ fọn kale lorilẹede yii. Nafdac wa di ẹbi isẹlẹ naa ru awọn olookowo to n pese ipara to n bo ara fawọn aralu lọna to lodi sofin. Ajọ naa ni ọpọ eroja majele fun agọ ara lawọn onisowo ibora naa n po papọ, eyi to le se ijamba fun awọ ara lode ati ninu. Oludari agba fajọ Nafdac, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye lo ke gbajare bẹẹ lasiko ifikunlukun ọlọjọ meji to waye nilu Eko. O ni asa ara bibo yii ti wa di gbajumọ laarin awọn ọkunrin ati obinrin ni Naijira, to si ti di tọrọ fọn kale. Adeyeye, ẹni to gbarata lori bawọn asaloge se n lo majele oloro fawọn onibara wọn lati fi bora tun salaye pe, awọn eroja yii ni wọn n ta lori ayelujara lowo gege. Bakan naa lo ni awọn onisowo to n polowo iku tantantan kiri ayelujara ọhun, tun maa n lẹdi apo pọ pẹlu awọn dokita onisegun oyinbo lati gun awọn to fẹ bora ni abẹrẹ. Adeyeye ni lara irufẹ abẹrẹ bẹẹ́ ni wọn lo ni eroja Vitamin C ati Glutathione ninu, eyi tawọn alaimọkan onibara yoo gba lati fi bo ara. Ọga agba fun Nafdac wa sisọ loju rẹ pe ọpọ eroja to ni majele ninu, ti wọn fi n po ọsẹ ati ipara ibora naa papọ, ni wọn n ko wọle lati oke okun. “Awọn eroja bii Kojic Acid ati Hydroquinone, ti odiwọn wọn kọja eyi to yẹ ko wọnu agọ ara, ni wọn ko fi orukọ wọn silẹ lọdọ ijọba, ti wọn si n ko wọle lati oke okun. Idi ree ti arun jẹjẹrẹ se di tọrọ fọn kale ni Naijiria nitori awọn majele yii lo n se okunfa rẹ ninu ara, tijọba si ti fofin de eroja Mercury fun ilo awọn asaraloge Bakan naa, ni awọn eroja ibora oni majele yii maa n se okunfa aisan Kidinrin ati ẹdọ fooro nitori pe o maa n gbogun ti wọn ninu agọ ara ni.’ O wa yan pe ara ti awọn eeyan ba bo loni lee se okunfa arun jẹjẹrẹ lọjọ ọla. O wa fi ewe ọmọ mọ awọn onisowo iku yii leti pe ki wọn jawọ ninu owo ti ko ni laada ọhun nitori ẹni ti ọwọ Nafdac ba tẹ ninu wọn, yoo foju bale ẹjọ, ti yoo si fi ẹwọn jura. “O nira fun Nafdac lati gba awọn olookowo ibora mu tori wọn kii patẹ rẹ” O wa gbarata pe o nira fun ajọ Nafdac lati tete gba awọn apanimayọda onisowo eroja ibora naa mu nitori kiamọsa ni wọn maa n pese eroja naa, ti wọn yoo si ta fun onibara loju ẹsẹ. O ni ọpọ wọn ni kii patẹ awọn eroja yii sori igba wọn, ki ọwọ awọn osisẹ Nafdac ma baa tẹ wọn. Adeyeye ni se ni awọn eeyan to n ko awọn eroja ti wọn n po papọ lati fi bo ara yi wọle lati oke okun, maa n gbe pamọ labẹ ilana Global Lisitng, gbe kọja lara Nafdac. Ọga agba fajọ Nafdac wa fi ọwọ gbaya pe ajọ naa ti n gbe igbesẹ lati fi awọn eeyan kan jofin lori iwa yii, ti ọwọ yoo si tẹ wọn laipẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cek8klzrzmyo |
2health
| Psychiatric Examination: iÌjọba ní kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ni ṣe àyẹ̀wò ọpọlọ f'áwọn Ọlọ́pàá àti agbófinró | Igbimọ alaṣẹ fun eto ọrọ aje Naijiria ti fẹnuko lẹyin ipade wọn pe ki awọn olori awọn oṣiṣẹ alaabo lorilẹede Naijiria rii daju pe wọn n ṣe ayẹwo ọpọlọ ati ti oogun oloro fun awọn oṣiṣẹ wọn. Eyi wa lara abajade ipade wọn to waye lọjọ Ẹti eyi ti igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo dari. Ninu ọrọ kan ti agbẹnusọ igbakeji aarẹ, Laolu Akande fi sita, o ni wọn gbudọ rii daju pe ilera ọpọlọ awọn eeyan wọn duro deede lati gbe ibọ̀n ati nkan ijagun. Ipade yii n waye ni ibamu pẹlu bi igbimọ naa ṣe rii pe awọn ọmọ Naijiria n gbero lati ṣe ayajọ iwọde ifẹhonuhan #EndSARS. Gẹgẹ bi ọkan lara awọn afẹhonuhan ṣe bere lọdun to kọja, igbimọ naa ni ki ijọba boju to alaafia awọn oṣiṣẹ eleto aabo. "Igbimọ NEC n pe gbogbo awọn adari oṣiṣẹ eleto aabo Naijiria lati rii pe awọn ti wọn ba n gba si iṣẹ eyi ti wọn yoo ti maa gbe ibọn lati ṣe ayẹwo ọpọlọ ati ti oogun oloro". Lẹyin ti wọn ba gba wọn wọle tan, igbimọ naa tun ni ki wọn maa ṣe ayẹwo ọhun loorekoore lẹnu iṣẹ. Igbimọ naa rọ ijọba Naijiria lati faaye silẹ fun igbeaye alafia awọn ọlọoaa atawọn oṣiṣẹ alaabo Naijiria. Ni pato, wọn pe fun ṣiṣe ayẹwo owo oṣu awọn oṣiṣẹfẹyinti to jẹ ọlọpaa ati riri owo awọn to wa lẹnu iṣẹ gba lasiko to yẹ. Bakan naa ni igbimọ yii tun gba awọn oṣiṣẹ alaabo ni imọran pe ki wọn maa tẹle ofin ti wọn fi gba wọn siṣẹ lasiko ti wọn ba wa lẹnu iṣẹ lagbegbe ibi ti wọn pin wọn si tabi nita. Nigba to n fun 'pe si awọn oṣiṣẹ alaabo lori ọgbọn amulo lati gbogun ti iwa ọdaran, igbimọ naa ni ki awọn ọlọpaa wa ni ibamu pẹlu ohun ti wọn pese latara ikọni abala ofin ileeṣẹ ọlpaa fun dun 2020. O ni ṣiṣe ikọni ati idanilẹkọ fun awọn ọlọpaa ṣe pataki fun iṣẹ wọn. Lafikun, igbimọ NEC ni awọn eeyan ti wọn timọle nitori iwọde EndSARS wa ni ibamu pẹlu ofin to de gbigbọra ẹni ye. O fi kun un pe wọn ni lati rii pe ilana ti wọn fi lelẹ laarin ileeṣẹ Ọlọpaa Naijiria lati maa fi yanju ẹsun ti awọn araalu ba mu wa kun oju osuwọn ki awọn ọlọpaa to ba ti wa lẹnu iṣẹ si maa wọ aṣọ. wọn pẹlu lilẹ orukọ wọn mọ aya. | Psychiatric Examination: iÌjọba ní kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ni ṣe àyẹ̀wò ọpọlọ f'áwọn Ọlọ́pàá àti agbófinró Igbimọ alaṣẹ fun eto ọrọ aje Naijiria ti fẹnuko lẹyin ipade wọn pe ki awọn olori awọn oṣiṣẹ alaabo lorilẹede Naijiria rii daju pe wọn n ṣe ayẹwo ọpọlọ ati ti oogun oloro fun awọn oṣiṣẹ wọn. Eyi wa lara abajade ipade wọn to waye lọjọ Ẹti eyi ti igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo dari. Ninu ọrọ kan ti agbẹnusọ igbakeji aarẹ, Laolu Akande fi sita, o ni wọn gbudọ rii daju pe ilera ọpọlọ awọn eeyan wọn duro deede lati gbe ibọ̀n ati nkan ijagun. Ipade yii n waye ni ibamu pẹlu bi igbimọ naa ṣe rii pe awọn ọmọ Naijiria n gbero lati ṣe ayajọ iwọde ifẹhonuhan #EndSARS. Gẹgẹ bi ọkan lara awọn afẹhonuhan ṣe bere lọdun to kọja, igbimọ naa ni ki ijọba boju to alaafia awọn oṣiṣẹ eleto aabo. "Igbimọ NEC n pe gbogbo awọn adari oṣiṣẹ eleto aabo Naijiria lati rii pe awọn ti wọn ba n gba si iṣẹ eyi ti wọn yoo ti maa gbe ibọn lati ṣe ayẹwo ọpọlọ ati ti oogun oloro". Lẹyin ti wọn ba gba wọn wọle tan, igbimọ naa tun ni ki wọn maa ṣe ayẹwo ọhun loorekoore lẹnu iṣẹ. Igbimọ naa rọ ijọba Naijiria lati faaye silẹ fun igbeaye alafia awọn ọlọoaa atawọn oṣiṣẹ alaabo Naijiria. Ni pato, wọn pe fun ṣiṣe ayẹwo owo oṣu awọn oṣiṣẹfẹyinti to jẹ ọlọpaa ati riri owo awọn to wa lẹnu iṣẹ gba lasiko to yẹ. Bakan naa ni igbimọ yii tun gba awọn oṣiṣẹ alaabo ni imọran pe ki wọn maa tẹle ofin ti wọn fi gba wọn siṣẹ lasiko ti wọn ba wa lẹnu iṣẹ lagbegbe ibi ti wọn pin wọn si tabi nita. Nigba to n fun 'pe si awọn oṣiṣẹ alaabo lori ọgbọn amulo lati gbogun ti iwa ọdaran, igbimọ naa ni ki awọn ọlọpaa wa ni ibamu pẹlu ohun ti wọn pese latara ikọni abala ofin ileeṣẹ ọlpaa fun dun 2020. O ni ṣiṣe ikọni ati idanilẹkọ fun awọn ọlọpaa ṣe pataki fun iṣẹ wọn. Lafikun, igbimọ NEC ni awọn eeyan ti wọn timọle nitori iwọde EndSARS wa ni ibamu pẹlu ofin to de gbigbọra ẹni ye. O fi kun un pe wọn ni lati rii pe ilana ti wọn fi lelẹ laarin ileeṣẹ Ọlọpaa Naijiria lati maa fi yanju ẹsun ti awọn araalu ba mu wa kun oju osuwọn ki awọn ọlọpaa to ba ti wa lẹnu iṣẹ si maa wọ aṣọ. wọn pẹlu lilẹ orukọ wọn mọ aya. | https://www.bbc.com/yoruba/58991399 |
2health
| Wo obìnrin tó bí ìbaàrún lẹ́yìn tó bí ìbejì lẹ́ẹ̀mejì àti ọmọ mẹ́sàn-án mìí | Awọn eeyan kan nipinlẹ Katsina ti bẹrẹ si ni pe arabinrin kan, Hajara Shuaibu, ni obinrin ti ọmọ pọ lara rẹ julọ ni Naijiria. Eyi waye lẹyin ti obinrin naa bi ọmọ marun-un lẹẹkan ṣoṣo ni Ọjọru. Ṣaaju asiko yii, Hajara ti kọkọ bi ibeji lẹẹmeji, ọmọ mẹsan-an miran, ko tun to bi marun-un. Hajara ba BBC sọrọ lori iriri rẹ to fi di iya ọlọmọ pupọ. Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni oun o ko mọ pe ọmọ to wa ninu oun ju ẹyọkan lọ, ati pe gbogbo nkan to yẹ ni oun ṣe ninu oyun. Hajara ko lọ si ileewosan ri fun itọju alaboyun, ante-natal, ile lo si bimọ si pẹlu iranlọwọ awọn iya agbẹbi ti wọn n pe ni Unguwan ni ede Hausa. Lẹyin to bimọ sile ni wọn to gbe e lọ si ileewosan Funtua General Hospital. O ni igba akọkọ ree ti wọn gbe oun lọ sileewosan nitori ọmọ bibi. Hajara sọ pe oun ko ni ounjẹ kan gboogi tabi asejẹ kankan to mu ki oun maa bimọ bẹẹ. Shuaibu Umar, to jẹ ọkọ Hajara sọ fun BBC pe meji lara awọn ọmọ tuntun naa kú lọjọ Ọjọbọ, to si ku mẹta ati iya wọn nileewosan ijọba apapọ nilu Katsina. “Nitori wọn ko ni irinṣẹ fun awọn ọmọ tuntun ti ko gbó nileewosan ni Funtua, ni wọn ṣe sọ pe ka gbe wọn lọ si Katsina fun itọju to peye.” Shuaibu to jẹ agbẹ ni abule Doma sọ pe ibukun ni oun ka ọmọ si lati ọdọ Ọlọrun. Bakan naa lo sọ pe alaga ijọba ibilẹ Faskari nipinlẹ Katsina, ti fi ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira ran wọn lọwọ. Ṣugbọn o ni awọn ṣi nilo iranlọwọ owo lati tọju ẹbi oun to jẹ elero pupọ. Nigba ti akọroyin BBC beere lọwọ Hajara boya yoo tun bimọ si, o ni ọwọ Ọlọrun ni eto aye oun wa. “To ba sọ pe kadara mi ni ki n tun bimọ si, dandan ni ko ri bẹẹ.” | Wo obìnrin tó bí ìbaàrún lẹ́yìn tó bí ìbejì lẹ́ẹ̀mejì àti ọmọ mẹ́sàn-án mìí Awọn eeyan kan nipinlẹ Katsina ti bẹrẹ si ni pe arabinrin kan, Hajara Shuaibu, ni obinrin ti ọmọ pọ lara rẹ julọ ni Naijiria. Eyi waye lẹyin ti obinrin naa bi ọmọ marun-un lẹẹkan ṣoṣo ni Ọjọru. Ṣaaju asiko yii, Hajara ti kọkọ bi ibeji lẹẹmeji, ọmọ mẹsan-an miran, ko tun to bi marun-un. Hajara ba BBC sọrọ lori iriri rẹ to fi di iya ọlọmọ pupọ. Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni oun o ko mọ pe ọmọ to wa ninu oun ju ẹyọkan lọ, ati pe gbogbo nkan to yẹ ni oun ṣe ninu oyun. Hajara ko lọ si ileewosan ri fun itọju alaboyun, ante-natal, ile lo si bimọ si pẹlu iranlọwọ awọn iya agbẹbi ti wọn n pe ni Unguwan ni ede Hausa. Lẹyin to bimọ sile ni wọn to gbe e lọ si ileewosan Funtua General Hospital. O ni igba akọkọ ree ti wọn gbe oun lọ sileewosan nitori ọmọ bibi. Hajara sọ pe oun ko ni ounjẹ kan gboogi tabi asejẹ kankan to mu ki oun maa bimọ bẹẹ. Shuaibu Umar, to jẹ ọkọ Hajara sọ fun BBC pe meji lara awọn ọmọ tuntun naa kú lọjọ Ọjọbọ, to si ku mẹta ati iya wọn nileewosan ijọba apapọ nilu Katsina. “Nitori wọn ko ni irinṣẹ fun awọn ọmọ tuntun ti ko gbó nileewosan ni Funtua, ni wọn ṣe sọ pe ka gbe wọn lọ si Katsina fun itọju to peye.” Shuaibu to jẹ agbẹ ni abule Doma sọ pe ibukun ni oun ka ọmọ si lati ọdọ Ọlọrun. Bakan naa lo sọ pe alaga ijọba ibilẹ Faskari nipinlẹ Katsina, ti fi ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira ran wọn lọwọ. Ṣugbọn o ni awọn ṣi nilo iranlọwọ owo lati tọju ẹbi oun to jẹ elero pupọ. Nigba ti akọroyin BBC beere lọwọ Hajara boya yoo tun bimọ si, o ni ọwọ Ọlọrun ni eto aye oun wa. “To ba sọ pe kadara mi ni ki n tun bimọ si, dandan ni ko ri bẹẹ.” | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cjr5vyzlwwvo |
4religion
| TB Joshua's death: Ìyàwó TB Joshua sọ bí ọkọ rẹ̀ ṣe kú àti òhun tó fà á | Evelyn to jẹ iyawo gbajugbaja Woli Temitope Balogun ti gbogbo eniyan mọ si TB Joshua, ti sọ bi ọkọ rẹ ṣe ku. Lasiko to n sọrọ, gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Post ti sọ, Evelyn ni TB Joshua lo igbẹyin aye rẹ lati fi gbadura fun awọn ara ilẹ India lori ohun ti wọn n la kọja lati igba ti aarun Coronavirus ti bẹ silẹ nibẹ. O ni Woli naa ni wọn ri ninu ọfisi rẹ to ti ku lẹyin to ṣe isin tan ni irọlẹ ọjọ Satide naa. Awọn ti wọn sunmọ iyawo oloogbe naa ni Evelyn sọ awọn ọrọ yii lasiko ti awọn eniyan lati ilẹ okeere ba obinrin naa ṣe ipade lẹyin iku ọkọ rẹ. ''Ọkọ mi ṣe iṣẹ rẹ tan ninu igbagbọ nitori wakati mẹta lo fi gbadura, ki o to lọ si isin ori oke, ti ilera ara rẹ si pe samu samu.'' ''Ko fi igba kankan fi ami han bi ẹni to n ṣe aisan, ti gbogbo ọrọ rẹ si da le lori gbigba adura fun awọn ara ilẹ India ti aarun covid-19 n ba finra.'' ''Ko pẹ si igba yii, ni o wa si yara lati wa wẹ, ti mo si fi silẹ ko lo akoko to nilo lati fi mura, ki isin to bẹrẹ. ''Laipẹ lo jade ninu ile lati lọ waasu laarin isin, to si sọ wi pe ohun gbogbo ni igba ati asiko wa fun, igba ki eniyan wa, ati igba ki eniyan lọ'' ''Ọrọ rẹ kun fun ẹmi ati ipaya nitori lọgan to sọ awọn ọrọ yii, naa lo dede kuro ni ile ijọsin to si lọ si inu ile. Mo duro fun igba diẹ lati wo boya yoo jade, nigba ti n ko gburo rẹ ni mo wọle, ti mo si ba lori ijoko bi ẹni to dorikodo, amọ ko mọ ara mọ.'' ''Ni kiakia ni mo pe awọn amugbalẹgbẹ rẹ ki wọn ji i, amọ ko si ohun ti wọn le ṣe lasiko naa.'' ''Mo gba lootọ wi pe o lọ ba Ọlọrun nile ni nitori o ṣiṣẹ takuntakun nigba ti o wa pẹlu wa, ti opin ọrọ rẹ si awọn eniyan ni lati ''ma a ṣọra, ki wọn si ma a gbadura''. Ọjọ Karun un, Oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ni gbajugbaja Woli agbaye TB Joshua jade laye ni ẹni ọdun mẹtadinlọgọta. | TB Joshua's death: Ìyàwó TB Joshua sọ bí ọkọ rẹ̀ ṣe kú àti òhun tó fà á Evelyn to jẹ iyawo gbajugbaja Woli Temitope Balogun ti gbogbo eniyan mọ si TB Joshua, ti sọ bi ọkọ rẹ ṣe ku. Lasiko to n sọrọ, gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Post ti sọ, Evelyn ni TB Joshua lo igbẹyin aye rẹ lati fi gbadura fun awọn ara ilẹ India lori ohun ti wọn n la kọja lati igba ti aarun Coronavirus ti bẹ silẹ nibẹ. O ni Woli naa ni wọn ri ninu ọfisi rẹ to ti ku lẹyin to ṣe isin tan ni irọlẹ ọjọ Satide naa. Awọn ti wọn sunmọ iyawo oloogbe naa ni Evelyn sọ awọn ọrọ yii lasiko ti awọn eniyan lati ilẹ okeere ba obinrin naa ṣe ipade lẹyin iku ọkọ rẹ. ''Ọkọ mi ṣe iṣẹ rẹ tan ninu igbagbọ nitori wakati mẹta lo fi gbadura, ki o to lọ si isin ori oke, ti ilera ara rẹ si pe samu samu.'' ''Ko fi igba kankan fi ami han bi ẹni to n ṣe aisan, ti gbogbo ọrọ rẹ si da le lori gbigba adura fun awọn ara ilẹ India ti aarun covid-19 n ba finra.'' ''Ko pẹ si igba yii, ni o wa si yara lati wa wẹ, ti mo si fi silẹ ko lo akoko to nilo lati fi mura, ki isin to bẹrẹ. ''Laipẹ lo jade ninu ile lati lọ waasu laarin isin, to si sọ wi pe ohun gbogbo ni igba ati asiko wa fun, igba ki eniyan wa, ati igba ki eniyan lọ'' ''Ọrọ rẹ kun fun ẹmi ati ipaya nitori lọgan to sọ awọn ọrọ yii, naa lo dede kuro ni ile ijọsin to si lọ si inu ile. Mo duro fun igba diẹ lati wo boya yoo jade, nigba ti n ko gburo rẹ ni mo wọle, ti mo si ba lori ijoko bi ẹni to dorikodo, amọ ko mọ ara mọ.'' ''Ni kiakia ni mo pe awọn amugbalẹgbẹ rẹ ki wọn ji i, amọ ko si ohun ti wọn le ṣe lasiko naa.'' ''Mo gba lootọ wi pe o lọ ba Ọlọrun nile ni nitori o ṣiṣẹ takuntakun nigba ti o wa pẹlu wa, ti opin ọrọ rẹ si awọn eniyan ni lati ''ma a ṣọra, ki wọn si ma a gbadura''. Ọjọ Karun un, Oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ni gbajugbaja Woli agbaye TB Joshua jade laye ni ẹni ọdun mẹtadinlọgọta. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57387890 |
4religion
| Sister Kate: Mò ń wọ ìjáàbù kí àwọn okùnrin má bà ṣìnà ìjọba ọ̀run nítorí bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí mi | Ajihinrere obinrin kan, Sister Catherine, ti ọpọ eeyan mọ si Sister kate ti sọrọ lori idi to ṣe n wọ ijaabu bo tilẹ jẹ pe kii ṣe Musulumi. Obinrin naa sọ pe oun bẹrẹ si n wọ ijaabu nitori awọn aṣọ ti oun maa n wọ tẹlẹ maa n gbe bẹbẹrẹ idi oun sita, o si le dena awọn okunrin lati wọ ijọba ọrun. Gẹgẹ bii oun to sọ, ọpọ eeyan lo ti maa n sọ fun oun tẹlẹ pe irufẹ awọn aṣọ ti oun maa n wọ ko bojumu gẹgẹ bii ọmọlẹyin Kristi, nitori o maa n gbe ara oun sita, o si le ṣe idena fun okunrin lọdọ Ọlọrun. Sister Kate ni ijaabu kii ṣe aṣọ awọn Musulumi gẹgẹ bii ọpọ eeyan ṣe gbagbọ, ṣubọn aṣọ awọn Kristẹni ti awọn Musulumi kan n yalo ni nitori o bojumu. Ninu fidio kan loju opo Youtube rẹ lo ti fi ọrọ naa lede. Ajihinrere obrinin naa ni "Lati igba ti mo ti n wọ ijaabu ni ọpọ eeeyan ti maa n pe mi ni Musulumi, amọ mi o kii ṣe Musulumi." "Lakọkọ, ọmọlẹyin Kristi ni mi, mo si ti di atunbi." "Iwe mimọ sọ ninu iwe Mathew 5:28 pe Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀." Arabinrin naa sọ siwaju si pe ni gbogbo igba ti oun ba n waasu ni awọn okunrin maa wo ibadi oun, eyii ti kii jẹ ki wọn tẹti si ọrọ Ọlọrun ti oun n ba wọn sọ. O ni lọpọ igba ni awọn okunrin ma n sọ pe ibadi oun n da wọn lọrun. Sister Kate tẹsiwaju pe "Koda, Ọlọrun ti ba mi sọrọ loju ala mi pe ki n dẹkun ati maa da awọn okunrin lọrun, idi ree ti mo fi n wọ ijaabu." Lẹyin naa lo gba awọn obinrin to maa n wọ aṣọ ati ṣokoto to maa n ṣi ara wọn silẹ nimọran lati dẹkun ṣiṣe bẹẹ. Bo tilẹ jẹ pe ko sọ pe ki awọn obinrin maa wọ ijaabu, o ni o yẹ ki wọn maa wọ awọn aṣọ ti yoo bo aṣiri ara wọn. | Sister Kate: Mò ń wọ ìjáàbù kí àwọn okùnrin má bà ṣìnà ìjọba ọ̀run nítorí bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí mi Ajihinrere obinrin kan, Sister Catherine, ti ọpọ eeyan mọ si Sister kate ti sọrọ lori idi to ṣe n wọ ijaabu bo tilẹ jẹ pe kii ṣe Musulumi. Obinrin naa sọ pe oun bẹrẹ si n wọ ijaabu nitori awọn aṣọ ti oun maa n wọ tẹlẹ maa n gbe bẹbẹrẹ idi oun sita, o si le dena awọn okunrin lati wọ ijọba ọrun. Gẹgẹ bii oun to sọ, ọpọ eeyan lo ti maa n sọ fun oun tẹlẹ pe irufẹ awọn aṣọ ti oun maa n wọ ko bojumu gẹgẹ bii ọmọlẹyin Kristi, nitori o maa n gbe ara oun sita, o si le ṣe idena fun okunrin lọdọ Ọlọrun. Sister Kate ni ijaabu kii ṣe aṣọ awọn Musulumi gẹgẹ bii ọpọ eeyan ṣe gbagbọ, ṣubọn aṣọ awọn Kristẹni ti awọn Musulumi kan n yalo ni nitori o bojumu. Ninu fidio kan loju opo Youtube rẹ lo ti fi ọrọ naa lede. Ajihinrere obrinin naa ni "Lati igba ti mo ti n wọ ijaabu ni ọpọ eeeyan ti maa n pe mi ni Musulumi, amọ mi o kii ṣe Musulumi." "Lakọkọ, ọmọlẹyin Kristi ni mi, mo si ti di atunbi." "Iwe mimọ sọ ninu iwe Mathew 5:28 pe Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀." Arabinrin naa sọ siwaju si pe ni gbogbo igba ti oun ba n waasu ni awọn okunrin maa wo ibadi oun, eyii ti kii jẹ ki wọn tẹti si ọrọ Ọlọrun ti oun n ba wọn sọ. O ni lọpọ igba ni awọn okunrin ma n sọ pe ibadi oun n da wọn lọrun. Sister Kate tẹsiwaju pe "Koda, Ọlọrun ti ba mi sọrọ loju ala mi pe ki n dẹkun ati maa da awọn okunrin lọrun, idi ree ti mo fi n wọ ijaabu." Lẹyin naa lo gba awọn obinrin to maa n wọ aṣọ ati ṣokoto to maa n ṣi ara wọn silẹ nimọran lati dẹkun ṣiṣe bẹẹ. Bo tilẹ jẹ pe ko sọ pe ki awọn obinrin maa wọ ijaabu, o ni o yẹ ki wọn maa wọ awọn aṣọ ti yoo bo aṣiri ara wọn. | https://www.bbc.com/yoruba/media-61282950 |
2health
| Buhari, Osinbajo ti gba abẹ́rẹ́ ajẹsára Covid-19 Oxford-AstraZeneca | Ni idahun si oniruuru ibeere ti awọn oniroyin n fi ṣọwọ si awọn oṣiṣẹ aarẹ Muhammadu Buhari lẹyin to gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19, agbẹnusọ aarẹ Buhari, femi Adesina ti fi ọrọ kan sita eyi ti oluranlọwọ pataki fun aarẹ Garba Shehu fọwọ si sita. "Mo fẹ fi da gobogbo araalu loju ati lati mu ibẹru ati igbagbọ odi kuro lọkan awọn eeyan nipa abo abẹrẹ ajẹsara ti wọn fun aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ". O ni lẹyin ti aarẹ gba tirẹ si apa tan, ara wa bo ṣe wa tẹlẹ to si tẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ. O ni bi ipalara kankan ba pada wa, awọn ko ni fi ohunkohun bo "ṣugbọn titi di asiko yii, ko si ipalara kankan yala o lagbara ni abi o kere lori aarẹ. O n ṣe ohun to yẹ ko ṣe". "A lero pe eyi yoo ṣeranwọ lati fi ọrọ to nipọn ranṣẹ si awọn eeyan paapaa julọ awọn to fi aifẹ gba tabi ọrọ boya o n ṣiṣẹ ati abo abẹrẹ ajẹsara naa ṣere". Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19. Eyi waye lẹyin ọjọ kan ti wọn bẹrẹ si ni fun awọn oṣiṣẹ eto ilera ni Naijiria ni abẹrẹ naa. Ile ijọba Aso Rock nilu Abuja ni aarẹ ati igbakeji rẹ ti gba ti wọn, wọn si ṣafihan eto naa lori amohunmaworan. Aarẹ Buhari sọ pe bi oun ṣe gba abala akọkọ abẹrẹ naa, oun rọ awọn ọmọ Naijiria to ni ẹtọ lati gba, ki awọn naa ṣe bẹ ẹ. Ọga agba ajọ eto ilera alabọde ni Naijiria, Dokita Faisal Shuaib sọ pe ireti wa pe bi aarẹ ṣe gba abẹrẹ ajẹsara naa yoo ṣe iwuri fun awọn araalu lati gba fun idaabo bo lọwọ Covid-19. Ọjọ Aje ni awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ Aarẹ Buhari yoo bẹrẹ si ni i gba, gẹgẹ bi ikede ti Dokita Shuaibu fi sita. Awọn oṣiṣẹ eto ilera ti di awọn eeyan akọkọ ti yoo gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ti Oxford-AstraZeneca ṣe ni Naijiria. Adari ileeṣẹ to n ri si eto ilera alabọde, Faisal Shuaib lo ṣide eto naa nibi to ti fun dọkita akọkọ labẹrẹ ọhun ni Naijiria, iyẹn Cyprian Nyong. Shuaib sọ pe awọn oṣiṣẹ eto ilera to n ṣiṣẹ julọ lasiko ti ajakalẹ arun naa milẹ titi lo kọkọ nilo abẹrẹ ọhun lati dabo bo wọn. Aadọjọ awọn oṣiṣẹ eto ilera miran yoo gba ọhun laipẹ lẹyin ti ajọ to n ṣakoso ounjẹ ati oogun lilo ti buwọlu. Eyii to n tumọ si pe kii ṣe Aarẹ Muhammadu Buhari ni yoo kọkọ gba abẹrẹ naa ni Naijiria gẹgẹ bo ṣe ri lawọn orilẹ-ede miran. Aarẹ Ghana, Nana Akufo-Addo lo kọkọ gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 lẹyin ọjọ kan to balẹ si orilẹ-ede ọhun. Lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun yii ni Aarẹ Buhari yoo gba abẹrẹ tirẹ, toun ti igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo. Bi eto abẹrẹ gbigba ọhun yoo ṣe lọ niyii; lẹyin ti awọn oṣiṣẹ eto ilera, Aarẹ ati igbakeji rẹ ba ti gba abẹrẹ tiwọn tan ni yoo kan awọn gomina. Ni kete ti awọn gomina ọhun ba ti gba abẹrẹ ọhun tan, lọjọ kejila, oṣu Kẹta, lati ṣafihan fun awọn awọn eeyan ipinlẹ wọn pe abẹrẹ naa ko mu ewu lọwọ ni yoo kan awọn ara ilu. Gbogbo awọn ipinlẹ ti ko ba kun oju oṣuwọn gbigba abẹrẹ naa, bii ẹrọ to le mu abẹrẹ ọhun tutu ko ni lanfani lati gba a. Ẹwẹ, gbogbo awọn ti yoo gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni Naijiria gbọdọ fi orukọ lẹ loju opo ti ijọba ti fi lọlẹ fun eto ọhun. | Buhari, Osinbajo ti gba abẹ́rẹ́ ajẹsára Covid-19 Oxford-AstraZeneca Ni idahun si oniruuru ibeere ti awọn oniroyin n fi ṣọwọ si awọn oṣiṣẹ aarẹ Muhammadu Buhari lẹyin to gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19, agbẹnusọ aarẹ Buhari, femi Adesina ti fi ọrọ kan sita eyi ti oluranlọwọ pataki fun aarẹ Garba Shehu fọwọ si sita. "Mo fẹ fi da gobogbo araalu loju ati lati mu ibẹru ati igbagbọ odi kuro lọkan awọn eeyan nipa abo abẹrẹ ajẹsara ti wọn fun aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ". O ni lẹyin ti aarẹ gba tirẹ si apa tan, ara wa bo ṣe wa tẹlẹ to si tẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ. O ni bi ipalara kankan ba pada wa, awọn ko ni fi ohunkohun bo "ṣugbọn titi di asiko yii, ko si ipalara kankan yala o lagbara ni abi o kere lori aarẹ. O n ṣe ohun to yẹ ko ṣe". "A lero pe eyi yoo ṣeranwọ lati fi ọrọ to nipọn ranṣẹ si awọn eeyan paapaa julọ awọn to fi aifẹ gba tabi ọrọ boya o n ṣiṣẹ ati abo abẹrẹ ajẹsara naa ṣere". Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19. Eyi waye lẹyin ọjọ kan ti wọn bẹrẹ si ni fun awọn oṣiṣẹ eto ilera ni Naijiria ni abẹrẹ naa. Ile ijọba Aso Rock nilu Abuja ni aarẹ ati igbakeji rẹ ti gba ti wọn, wọn si ṣafihan eto naa lori amohunmaworan. Aarẹ Buhari sọ pe bi oun ṣe gba abala akọkọ abẹrẹ naa, oun rọ awọn ọmọ Naijiria to ni ẹtọ lati gba, ki awọn naa ṣe bẹ ẹ. Ọga agba ajọ eto ilera alabọde ni Naijiria, Dokita Faisal Shuaib sọ pe ireti wa pe bi aarẹ ṣe gba abẹrẹ ajẹsara naa yoo ṣe iwuri fun awọn araalu lati gba fun idaabo bo lọwọ Covid-19. Ọjọ Aje ni awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ Aarẹ Buhari yoo bẹrẹ si ni i gba, gẹgẹ bi ikede ti Dokita Shuaibu fi sita. Awọn oṣiṣẹ eto ilera ti di awọn eeyan akọkọ ti yoo gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ti Oxford-AstraZeneca ṣe ni Naijiria. Adari ileeṣẹ to n ri si eto ilera alabọde, Faisal Shuaib lo ṣide eto naa nibi to ti fun dọkita akọkọ labẹrẹ ọhun ni Naijiria, iyẹn Cyprian Nyong. Shuaib sọ pe awọn oṣiṣẹ eto ilera to n ṣiṣẹ julọ lasiko ti ajakalẹ arun naa milẹ titi lo kọkọ nilo abẹrẹ ọhun lati dabo bo wọn. Aadọjọ awọn oṣiṣẹ eto ilera miran yoo gba ọhun laipẹ lẹyin ti ajọ to n ṣakoso ounjẹ ati oogun lilo ti buwọlu. Eyii to n tumọ si pe kii ṣe Aarẹ Muhammadu Buhari ni yoo kọkọ gba abẹrẹ naa ni Naijiria gẹgẹ bo ṣe ri lawọn orilẹ-ede miran. Aarẹ Ghana, Nana Akufo-Addo lo kọkọ gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 lẹyin ọjọ kan to balẹ si orilẹ-ede ọhun. Lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun yii ni Aarẹ Buhari yoo gba abẹrẹ tirẹ, toun ti igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo. Bi eto abẹrẹ gbigba ọhun yoo ṣe lọ niyii; lẹyin ti awọn oṣiṣẹ eto ilera, Aarẹ ati igbakeji rẹ ba ti gba abẹrẹ tiwọn tan ni yoo kan awọn gomina. Ni kete ti awọn gomina ọhun ba ti gba abẹrẹ ọhun tan, lọjọ kejila, oṣu Kẹta, lati ṣafihan fun awọn awọn eeyan ipinlẹ wọn pe abẹrẹ naa ko mu ewu lọwọ ni yoo kan awọn ara ilu. Gbogbo awọn ipinlẹ ti ko ba kun oju oṣuwọn gbigba abẹrẹ naa, bii ẹrọ to le mu abẹrẹ ọhun tutu ko ni lanfani lati gba a. Ẹwẹ, gbogbo awọn ti yoo gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni Naijiria gbọdọ fi orukọ lẹ loju opo ti ijọba ti fi lọlẹ fun eto ọhun. | https://www.bbc.com/yoruba/56296218 |
2health
| Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àrùn Ebola àti bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àrùn náà | Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun ni Africa, CDC, ti sọ pe oun ti n ṣeto lati jiroro pẹlu awọn ileeṣẹ apoogun oyinbo, to ti ṣe abẹrẹ ajẹsara to ṣe e ṣe ko koju ẹda aarun Ebola tuntun, Sudan Strain. Oludari ajọ CDC, Dokita Ouma Ogwell, sọ ni Ọjọbọ pe ti awọn ba fi ṣe aṣeyọri lori igbesẹ naa, ni kiakia ni awọn yoo bẹrẹ lilo abẹrẹ naa fun itọju pajawiri ni Uganda. Lọwọlọwọ, o ti pe eeyan mọkanlelọgbọn to ni ẹda aarun Ebola, Sudan strain naa, ti mẹfa lara wọn si ti ku ni Uganda. Ileeṣẹ eto ilera orilẹ-ede naa sọ pe ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ ilera to ko aarun naa wa bayii. Ebola jẹ arun buburu kan to maa n mu iba lọwọ, pẹlu ara riro. Yoo maa rẹ ẹni to ba ni arun naa, bẹẹ si ni irufẹ ẹni bẹẹ, ọna ọfun yoo maa dun un. Ti arun ọhun ba ti wọ eeyan lara, irufẹ ẹni bẹẹ yoo maa bi, bẹẹ si ni yoo maa ya igbẹ gburu. Nigba miran ẹwẹ, ẹjẹ le maa jade lara ẹni to ba ni arun Ebola. Ara ẹranko to ti ni arun naa tẹlẹ lo ti maa n ran eeyan, amọ ara ẹran igbẹ ti awọn eeyan n jẹ ni arun ọhun sodo si julọ. Lati ibẹ lọ o le ran awọn ẹlomiran nipasẹ omi ara bii ẹjẹ, itọ́, eebi, atọ ọṃkunrin tabi ti obinrin, igbọnsẹ ati ooru. Iwadii ijinlẹ ti fi han pe arun ọhun ṣi le wa ninu atọ ọkunrin lẹyin to ba ti gbawosan tan. Ọna kan gboogi lati daabo bo ara ẹni lọwọ Ebola ni lati ṣọra fun ẹni to ba ti ni arun naa lara. Maṣe bọwọ pẹlu ẹni to ba ni arun naa rara, fifọ ọwọ ẹni pẹlu omi ati ọṣẹ naa ṣe pataki. Awọn oṣiṣẹ eto ilera gbọdọ wọn aṣọ atawọn ohun idaabo bo ara ẹni miran ti wọn ba fẹ ṣe itọju alaarun Ebola. | Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àrùn Ebola àti bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àrùn náà Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun ni Africa, CDC, ti sọ pe oun ti n ṣeto lati jiroro pẹlu awọn ileeṣẹ apoogun oyinbo, to ti ṣe abẹrẹ ajẹsara to ṣe e ṣe ko koju ẹda aarun Ebola tuntun, Sudan Strain. Oludari ajọ CDC, Dokita Ouma Ogwell, sọ ni Ọjọbọ pe ti awọn ba fi ṣe aṣeyọri lori igbesẹ naa, ni kiakia ni awọn yoo bẹrẹ lilo abẹrẹ naa fun itọju pajawiri ni Uganda. Lọwọlọwọ, o ti pe eeyan mọkanlelọgbọn to ni ẹda aarun Ebola, Sudan strain naa, ti mẹfa lara wọn si ti ku ni Uganda. Ileeṣẹ eto ilera orilẹ-ede naa sọ pe ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ ilera to ko aarun naa wa bayii. Ebola jẹ arun buburu kan to maa n mu iba lọwọ, pẹlu ara riro. Yoo maa rẹ ẹni to ba ni arun naa, bẹẹ si ni irufẹ ẹni bẹẹ, ọna ọfun yoo maa dun un. Ti arun ọhun ba ti wọ eeyan lara, irufẹ ẹni bẹẹ yoo maa bi, bẹẹ si ni yoo maa ya igbẹ gburu. Nigba miran ẹwẹ, ẹjẹ le maa jade lara ẹni to ba ni arun Ebola. Ara ẹranko to ti ni arun naa tẹlẹ lo ti maa n ran eeyan, amọ ara ẹran igbẹ ti awọn eeyan n jẹ ni arun ọhun sodo si julọ. Lati ibẹ lọ o le ran awọn ẹlomiran nipasẹ omi ara bii ẹjẹ, itọ́, eebi, atọ ọṃkunrin tabi ti obinrin, igbọnsẹ ati ooru. Iwadii ijinlẹ ti fi han pe arun ọhun ṣi le wa ninu atọ ọkunrin lẹyin to ba ti gbawosan tan. Ọna kan gboogi lati daabo bo ara ẹni lọwọ Ebola ni lati ṣọra fun ẹni to ba ti ni arun naa lara. Maṣe bọwọ pẹlu ẹni to ba ni arun naa rara, fifọ ọwọ ẹni pẹlu omi ati ọṣẹ naa ṣe pataki. Awọn oṣiṣẹ eto ilera gbọdọ wọn aṣọ atawọn ohun idaabo bo ara ẹni miran ti wọn ba fẹ ṣe itọju alaarun Ebola. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cd1q3zk437lo |
3politics
| Sowore: Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí ìjọba àpapọ̀ san ₦1m owó ẹ̀bẹ̀ fún ẹgbẹ́ ajijagbara Sowore, torí ìwọde wọn tí wọ́n dà rú | Ilé ẹjọ́ gíga tí ìjọba àpapọ̀ tó wà n'ilu Eko ti pàṣẹ fún ìjọba láti san mílíọ̀nù kan náírà fún ẹgbẹ́ ajijagbara Revolution Now, lórí bo se da ìwọde ẹgbẹ́ náà ru ni ọjọ́ Kàrún oṣù Kẹjọ ọdún 2019. Agbẹjọro kan tó kopa ninu ìwọde náà, Olukoya Ogungbeje, ló wọ ìjọba lọ sílè ẹjọ́, lórí ẹ̀sùn pé àwọn òṣìṣẹ́ alaabo yín afẹ́fẹ́ tajú-tajú sì òun àti àwọn èèyàn yókù to ń ṣe ìwọde lójú. Ilé ẹjọ́, tó ní Ogungbeje jàre ẹjọ́ ọhun, tún pàṣẹ fún ìjọba àpapọ̀ láti tọrọ aforijin lọ́wọ́ olupẹjọ náà, lójú ewé ìwé ìròyìn mẹta nilẹ wá. Adajọ Maureen Onyetenu, tún kéde pé bí ijọba àpapọ̀, láti ipasẹ àwọn Ọlọpaa ṣe da ìwọde náà ru "kò bófin mú, ìwà ìjẹgàba ni, kò bá ìlànà ìjọba alagbada mú, tó sì tún tako àmúlò òfin ilẹ wa". Bákan náà ni adajọ Onyetenu gbà pé, ìjọba fi ẹtọ Ogungbeje to pé ẹjọ́ ní orúkọ àwọn Oluwọde yoku dùn wọn, nítorí abala kejidinlogoji, ikokandinlogoji àti ogójì òfin ilẹ̀ wá ti ọdún 1999, tí fun wọn ní àǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Adajọ náà tún korò ojú sì bí awọn agbofinro ṣe gbé àwọn oluwode náà lọpọ yanturu, tá àbùkù wọn, fín afẹ́fẹ́ tajú-tajú sì wọn lójú àti fífi wọn sínú túbú. Ọga patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ€de Naijiria, Mohammed Adamu ti ke si araalu pe ẹnikẹni to ba ṣiwọ lu ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ rẹ yoo jẹ iyan rẹ niṣu ni. Ọga ọlọpaaAdamu sọ ọrọ yii ninu esi rẹ lori arabinrin kan to kọlu ọga ọlọpaa kan ni ilu Eruwa ni ipinlẹ Ọyọ. Ọga ọlọpaa naa ti wọn pe orukọ rẹ ni ASP Adeyẹmọ Ogunyẹmi lo lọ si agbegbe Gbọlaguntẹ Okeọola ni Eruwa iyẹn nijọba ibilẹ Ibarapa East ni ipinlẹ Ọyọ lati lọ fidi ofin konile o gbele mulẹ nibẹ. Nibẹ ni arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Kẹhinde Afolakẹ ti kọluu to si soo laṣọ mu. Igbaju igbamu ni arabinrin naa fi ṣe ọga ọlọpaa naa lọjọ. Ẹ wo fidio naa: Ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria tun ṣalaye siwaju sii pe nigba ti wọn tun ranṣẹ pe arabinrin yii ni ọjọ keji pe ko wa wi tẹnu rẹ lori bi o ṣe kọlu ọga ọlọpaa naa, nṣe lo tun mu awọn ọlọpaa obinrin mejeeji Ripẹtọ Ojola Abiola ati Queen Eguaje ti wọn ran sii lu, koda o tun ge ọkan ninu wọn jẹ pẹlu. Ọga ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria wa ke si kọmiṣọna ọlọpaa lati ṣe iwadii si iṣẹlẹ naa lati lee gbe igbesẹ to ba ts ni ibamu pẹlu ofin. Bakan naa lo kan sara si ọga ọlọpaa Adeyẹmọ fun iwa ọmọluabi ati ikora-ẹni-ni-ijanu to hu pẹlu bi obinrin yii ṣe n luu to lọjọ naa. O ni eyi jẹ apẹrẹ oniruru ikọlu ti awọn ọlọpaa n dojukọ lẹnu iṣẹ wọn Amọṣa ọga ọlọpaa patapata lorilẹ€de Naijiria ni ko si ẹnikẹni to ba tun ṣiwọ lu ọlọpaa to n ṣe iṣẹ rẹ mọ lorilẹede Naijiria ti ko ni jẹ iyan rẹ ni iṣu. O ni ko din ni ọlọpaa mẹtadinlọgbọn tawọn eeyan bii arabinrin Afọlakẹ ti kọlu lati igba ti ajakalẹ arun COVID-19 yii ti bẹrẹ, ọpọlọpọ ninu wọn lo si ti di ero ileewosan ninu eyi ti wọn ko tii bọ di bi a ṣe n sọrọ yii. Laarin asiko ti a n sọrọ rẹ yii naa, ọkọ ọlọpaa bii marundinlogun ni awọn eeyan kan ti bajẹ, pẹlu ileeṣẹ ọẹọpaa meji ni Katsina ati Abia ni awọn eeyan kan ti dana sun. Ilumọọka adẹrinposonu lórí ayelujara, Oluwatoyin Bayegun, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ si Wòlíì Arole, tí ṣàlàyé pé ore-ọ̀fẹ́ àti àánú Ọlọ́run ló gbé òun sókè. O sọ nipa irinajo rẹ láti ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì ti òun ti bẹ̀rẹ̀ awada lórí ayelujara. Wòlíì Arole, lásìkò to ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé, isẹ awada sise tí gbé òun de ibi gíga, tí òun kò lérò pé òun leè de rí, tí òun ṣi tún mọ àwọn èèyàn ńlá-ńlá pẹ̀lú. "Mo ti lọ sí ilé aarẹ Nàìjíríà, Aso Rock ni ẹẹmeji, ìyàwó Buhari gan tí fun mi ni àmì ẹyẹ rí, mo sì máa ń lọ silu oyinbo loore koore, láti ipasẹ awada yìí náà ni." Wòlíì Arole ni "ọpọ ni kò fẹ́ kọ́kọ́ tẹ́wọ́ gba mi nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀, wọn ní èdè Yorùbá ni mo ń sọ àmọ́ nígbà tí kìí se àwọn ni Ọlọ́run, mo rí ọ̀nà àbáyọ." Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìpènijà tó ti là kọjá sẹ́yìn, Wòlíì Arole ni ọjọ́ kan wà tí wọn gba òun sì ẹgbẹ́ níbi ayẹyẹ kan torí pé òun kò tíì ní òkìkí nígbà náà àmọ́ òun dúpẹ́ fún ibi tí Ọlọ́run mú òun de lónìí. " Ẹ̀jẹ̀ mi ni Jésù, n kò sì tíì dé ibi tó ń mú mi lọ. Mo sì ń rọ àwọn èèyàn láti mase ro ara wọn pín, tàbí mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn wọn nitori ohun tí àwọn ènìyàn ba n sọ. Ọlọ́run ní kẹ gbé ọkàn yín lé, torí ohun ènìyàn kọ ni ohùn Ọlọ́run." O wa ṣàlàyé pé "Ọlọ́run ran iya mi sì mi. Òrìṣà ni ìyá mi, kii se ènìyàn. Mo fẹ́ràn ìyá mi gan-an ni, Kò sì sí Wòlíì Arole lai si ọwọ màmá mi nibẹ. Ó mọ mi denudenu, to sì fẹ́ràn mi tọkàntọkàn, tí ọkàn mi bá sì rẹ̀wẹ̀sì, ìyá mi lo máa ń tú mi nínú." Wòlíì Arole ni, ẹ̀bùn ni awada òun, tí ayé fi ń ko o jẹ, òun kii sì roo awada ti tẹ́lẹ̀, kí òun tó sọ síta, èyí tó máa ń jẹ ìtẹ́wọ́gbà lọdọ aráyé. Arole ni òun kò tíì ní ìyàwó nílé, àmọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ni yóò dárí òun lati darí isẹ àti ìdílé òun, lásìkò ti oun bá ní ìdílé. "O wu mi kì ń ṣe sinima àti show tèmi, kí n sì ni studio tèmi náà, Bẹ́ẹ̀ si ni èdè òyìnbó yọ lẹ́nu mi pẹ̀lú, bí mo ṣe leè ṣe awada ni ojúlówó èdè Yoruba náà ni awada tún dùn lẹ́nu mi ni èdè gẹ̀ẹ́sì, mo sì ni eto fún méjèèjì pẹ̀lú ni ọjọ́ iwájú." Arole wá rọ àwọn olólùfẹ́ rẹ láti jókòó sínú ilé wọn lásìkò igbele Coronavirus yìí, kí wọn sì mú gbogbo ìmọ̀ràn àti arọwa tí ìjọba ń pa fún wọn lọ nítorí ẹ̀mí kò ní ààrọ̀. Oluwadamilola Adeboye, tíì ṣe ọmọbìnrin gbajugbaja adẹrinposonu nnì, Gbenga Adeboye, tí sọ àwọn ìrírí tó sì rántí nípa bàbá rẹ̀ tó ti di olóògbé. Bẹẹ bá gbàgbé, Gbenga Adeboye lo jáde láyé ni ọgbọnjọ oṣù kẹrin ọdún 2003, èyí tó pé ọdún mẹtadinlogun lonii Ọjọ́bọ. Nígbà tó ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ láti sàmì ayajọ ìrántí ikú olóògbé náà, Oluwadamilola ni bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kéré pupọ nígbà tí bàbá òun kú, àmọ́ òun leè ṣe àpèjúwe rẹ bíi ẹni tó gbé aye ṣe rere. Oluwadamilola ni òun kò mọ ibi tí bàbá òun ti rí ẹ̀bùn tó ni àmọ́ ó fikùn pé, àwọn ẹ̀bùn rẹ náà kasiara, tó sì tún ya ní lẹ́nu pupọ. O ṣàlàyé pé nígbà tí bàbá òun wà láyé, ojoojumọ ni ile àwọn máa ń kùn, tí àwọn èèyàn máa ń wa, táwọn yóò sì gba àlejò, tí bàbá òun yóò sì máa ń ṣe awada pẹlu wọn, tí inú àwọn èèyàn yóò sì máa dùn, tí wọn kò sì ní fẹ́ kúrò nínú ilé àwọn. "Mo sì lee rántí pé Baba mi jẹ́ èèyàn rere, kò si ẹni ti kii se oore fún, kò si mọ bá ṣe ń kọ láti ṣe nkan fún èèyàn, tí onitọun bá nílò iranlọwọ." Nígbà miran ti bàbà mi bá dé sílè láti ibi tó ti lọ dá ẹrin posonu, tí a kò si ni oúnjẹ nílé, bí màmá mi bá béèrè pé owó tó mú bọ dà, yóò dáhùn pé òun ti pín owó náà fún àwọn tí ebi ń pá, tí yóò sì ní ká lọ mu gàárì, òun yóò fún wa lowo lọ́la láti fi ṣe irẹsi." Ọmọbìnrin Gbenga Adeboye náà fikùn pé, Baba òun ni ifẹ gbogbo ènìyàn bíi ọmọ àti àbúrò rẹ ni, ó sì tẹ bàbá òun lọrun pé ki awọn ẹbi rẹ mu gàárì kí àwọn ará ìta leè rí oúnjẹ jẹ, tàbí rí owó fún àwọn èèyàn. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí àwọn ẹbí fẹ́ máa fi ṣe irántí Gbenga Adeboye, Oluwadamilola ni "èmi àti màmá pẹ̀lú àwọn àbúrò mi ti pinnu láti máa ṣe atilẹyin fún àwọn osere tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde nilẹ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, ní kété tí ajakalẹ àrùn Coronavirus bá ti tan." O fikùn pé, àwọn yóò ṣe iranwọ fún àwọn osere tíátà lobinrin àti àwọn aláìní pẹ̀lú nítorí ohun tó máa ń mú inú bàbá òun dùn nìyẹn, èyí tíì ṣe fífún àwọn aláìní ni oúnjẹ.Bákan náà lo fikun pé ní ọjọ́ iwájú, tí àwọn bá tún ní erongba miran ti àwọn fẹ́ ṣe fún ìrántí Adeboye, àwọn yóò kéte síta. Ilumọọka olorin takasufe Davido ti kọ iwe ifẹ kan ṣọwọ si afẹsọna rẹ ati ọmọ wọn ni ọjọ ibi Chioma to n waye lọjọbọ Eyi wa loju opo Instagram rẹ. Mo ki obinrin to lagbara kulọ lara awọn ti mo mọ ku ọjọ ibi. Ka ni ko si ofin konile o gbele ni, awa mejeeji o ba ti jaye ori wa daada kaakiri igboro loni Iyawo mi tootọ, ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ yoo larinrin bi iwọ pẹlu ti ṣe mu ọpọlọpọ ayọ wọ inu aye mi. O ti le ni ọdun meji bayii ti Davido ati Chioma ti bẹrẹ irinajo ifẹ wọn ti Eleduwa si ti fi ọmọkunrin kan tawọn lọrẹ. Laipẹ yii ni Chioma bọ lọwọ arun Coronavirus lẹyin ọpọlọpọ ọjọ ti aisan naa fi daa wolẹ. Gbajugbaja akọrin takasufe ni, David Adeleke ti ọpọlọpọ mọ si Davido ti pariwo sita pe nnkan ko rẹrin lori titọju ọmọ ti oun ti iyawo rẹ Chioma bi fun latigba ti iya rẹ ti wa ni igbele iyasọtọ. Chioma, iyawo Davido ko arun Coronavirus eleyi ti ọkọ rẹ, Davido kede faye ni ọsẹ to kọja. Ninu ọrọ kan to fi sita loju opo twitter rẹ Davido lọgun pe iṣẹ l'abiyamọ n ṣe. Lẹyin ti ayẹwo fihan pe Chioma ti ko arun Coronavirus, igba meji ọtọọtọ ni Davido ni oun ti ṣe ayẹwo lati lee mọ boya oun ni arun naa tabi oun ko ni. Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alaaji Adegboyega Oyetọla ti ke gbajare sita pe awọn abọde lati orilẹede Côte d'Ivoire ni wọn jẹ ki ajakalẹ arun Coronavirus tubọ gogo sii ni ipinlẹ naa. Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ lori ẹrọ ibanisọrọ lẹyin ti ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun tun kede eeyan mẹsan miran pẹlu arun Korona ni ipinlẹ Ọṣun lọjọru, Gomina Oyetọla ṣalaye pe arun Korona ki ba ti burẹkẹ to bayii kani ijọba apapọ tete ti gbogbo ẹnuibode ni ki wọn si paṣẹ konileogbele fun gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria. Gomina Oyetọla ṣalaye siwaju sii pe, awọn ọmọ ipinlẹ naa ti wọn n ti orilẹede Côte d'Ivoire bọ wa sile ni wọn ko arun naa dani to fi di pe o tubọ peleke sii nipinlẹ naa. O wa rọ awsn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati fidimọle gẹgẹ bi aṣẹ ti ijọba pa lati lee wagbo dẹkun si wahala yii. Bakan naa ni o fi to wa leti pe lọna ati lee dẹkun ọwọja ebi ati inira lasiko aṣẹ konileogbele naa, ijọba oun ti gbe awọn igbesẹ ti yoo bu omi tu araalu lara bii sisanwo oṣu fun awọn oṣiṣẹ ki wọn to gbe aṣẹ naa kalẹ ati idasilẹ igbims majẹobajẹ kan lori ọna ati gbogun ti arun naa ati lati mu irọrun ba araalu lasiko ti wọn ba fi n baa wọ iyaaja. Ẹkunrẹrẹ wa ninu ohun ti a ka silẹ loke yii. Gbajugbaja akọrin takasufe, Divid Adeleke ti ọpọ eeyan mọ si Davido tun ti wẹ yan kainkain lọwọ arun coronavirus. Ọpọ ẹnu lo ti n kun Davido lẹyin ti iroyin jade pe ọpọ awọn eeyan to sun mọọ lo ti n ni arun yi lara. Ni ọjọ diẹ sẹyin ni Davido funrarẹ gbe iroyin jade pe iyawo oun, Chioma ti ko arun Coronavirus, bakan naa si ni gomina Seyi Makinde pẹlu kede pe oun pẹlu ti ni arun naa lẹyin ọjọ diẹ to gbalejo Davido ni ile ijọba nilu Ibadan. Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo twitter rẹ ni ọsan ọjọ Ọjọru, Davido ni oun ti tun ayẹwo arun Coronavirus ṣe o, ṣaka bayii si ni ara oun ya. Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde kede ni aṣalẹ ọjọ Aje pe oun ti ko arun Coronavirus ti o n ja kale-ka'ko bayii. O fi si oju opo twitter rẹ pe esi ayẹwo oun ti de ko si si ẹja n bakan kankan lori rẹ nitori ẹja lo ba de. Lẹyin eyi ni o ṣalaye pe gbogbo awọn to ti ni nnkan n ba oun ṣe laarin asiko ti oun fi lọ sibi ipade igbimọ ọrọ aje orilẹede Naijiria si ọjọ ti oun bẹrẹ igbele ni wọn ti n wa; koda iroyin kan tilẹ ss pe gbogbo awọn to baa da nnkan pọ laarin asiko naa, paapaa awọn kọmiṣọna atawọn amugbalẹgbẹ rẹ gbogbo ni wọn ti wa ni igbele bayii lati lee mọ boya awọn naa ko abi rara. Nibayii, BBC News Yoruba ṣe atupalẹ bi irinajo Gomina Seyi Makinde ṣe lọ laarin akoko naa ati awọn eeyan to ṣeeṣe ki wọn ti ko arun yii lati ara rẹ. Ẹ maa gbagbe pe eyi ko tumọ si pe gbogbo awọn eeyan to wa nibi eto wọnyii lo ti koo, ṣugbọn iwadi ati ayẹwo to gbọngbọn nikan lo lee fi idi eyi mulẹ. Fun apẹrẹ, gomina Makinde ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe asiko kan naa ni esi ayẹwo oun ati ti akọwe ijọba ipinlẹ naa, arabinrin Olubamiwo Adeosun de. Esi ti gomina lo jasi bẹẹni ti ti akọwe ijọba ipinlẹ naa si ja si bẹẹkọ. Idi ti awọn onimọ maa fi n ṣe ato irinajo ẹni to ba ni arun yii ni lati mọ ibi ti wọn lee wa awọn to lee ti koo lati ara wọn si. | Sowore: Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí ìjọba àpapọ̀ san ₦1m owó ẹ̀bẹ̀ fún ẹgbẹ́ ajijagbara Sowore, torí ìwọde wọn tí wọ́n dà rú Ilé ẹjọ́ gíga tí ìjọba àpapọ̀ tó wà n'ilu Eko ti pàṣẹ fún ìjọba láti san mílíọ̀nù kan náírà fún ẹgbẹ́ ajijagbara Revolution Now, lórí bo se da ìwọde ẹgbẹ́ náà ru ni ọjọ́ Kàrún oṣù Kẹjọ ọdún 2019. Agbẹjọro kan tó kopa ninu ìwọde náà, Olukoya Ogungbeje, ló wọ ìjọba lọ sílè ẹjọ́, lórí ẹ̀sùn pé àwọn òṣìṣẹ́ alaabo yín afẹ́fẹ́ tajú-tajú sì òun àti àwọn èèyàn yókù to ń ṣe ìwọde lójú. Ilé ẹjọ́, tó ní Ogungbeje jàre ẹjọ́ ọhun, tún pàṣẹ fún ìjọba àpapọ̀ láti tọrọ aforijin lọ́wọ́ olupẹjọ náà, lójú ewé ìwé ìròyìn mẹta nilẹ wá. Adajọ Maureen Onyetenu, tún kéde pé bí ijọba àpapọ̀, láti ipasẹ àwọn Ọlọpaa ṣe da ìwọde náà ru "kò bófin mú, ìwà ìjẹgàba ni, kò bá ìlànà ìjọba alagbada mú, tó sì tún tako àmúlò òfin ilẹ wa". Bákan náà ni adajọ Onyetenu gbà pé, ìjọba fi ẹtọ Ogungbeje to pé ẹjọ́ ní orúkọ àwọn Oluwọde yoku dùn wọn, nítorí abala kejidinlogoji, ikokandinlogoji àti ogójì òfin ilẹ̀ wá ti ọdún 1999, tí fun wọn ní àǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Adajọ náà tún korò ojú sì bí awọn agbofinro ṣe gbé àwọn oluwode náà lọpọ yanturu, tá àbùkù wọn, fín afẹ́fẹ́ tajú-tajú sì wọn lójú àti fífi wọn sínú túbú. Ọga patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ€de Naijiria, Mohammed Adamu ti ke si araalu pe ẹnikẹni to ba ṣiwọ lu ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ rẹ yoo jẹ iyan rẹ niṣu ni. Ọga ọlọpaaAdamu sọ ọrọ yii ninu esi rẹ lori arabinrin kan to kọlu ọga ọlọpaa kan ni ilu Eruwa ni ipinlẹ Ọyọ. Ọga ọlọpaa naa ti wọn pe orukọ rẹ ni ASP Adeyẹmọ Ogunyẹmi lo lọ si agbegbe Gbọlaguntẹ Okeọola ni Eruwa iyẹn nijọba ibilẹ Ibarapa East ni ipinlẹ Ọyọ lati lọ fidi ofin konile o gbele mulẹ nibẹ. Nibẹ ni arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Kẹhinde Afolakẹ ti kọluu to si soo laṣọ mu. Igbaju igbamu ni arabinrin naa fi ṣe ọga ọlọpaa naa lọjọ. Ẹ wo fidio naa: Ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria tun ṣalaye siwaju sii pe nigba ti wọn tun ranṣẹ pe arabinrin yii ni ọjọ keji pe ko wa wi tẹnu rẹ lori bi o ṣe kọlu ọga ọlọpaa naa, nṣe lo tun mu awọn ọlọpaa obinrin mejeeji Ripẹtọ Ojola Abiola ati Queen Eguaje ti wọn ran sii lu, koda o tun ge ọkan ninu wọn jẹ pẹlu. Ọga ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria wa ke si kọmiṣọna ọlọpaa lati ṣe iwadii si iṣẹlẹ naa lati lee gbe igbesẹ to ba ts ni ibamu pẹlu ofin. Bakan naa lo kan sara si ọga ọlọpaa Adeyẹmọ fun iwa ọmọluabi ati ikora-ẹni-ni-ijanu to hu pẹlu bi obinrin yii ṣe n luu to lọjọ naa. O ni eyi jẹ apẹrẹ oniruru ikọlu ti awọn ọlọpaa n dojukọ lẹnu iṣẹ wọn Amọṣa ọga ọlọpaa patapata lorilẹ€de Naijiria ni ko si ẹnikẹni to ba tun ṣiwọ lu ọlọpaa to n ṣe iṣẹ rẹ mọ lorilẹede Naijiria ti ko ni jẹ iyan rẹ ni iṣu. O ni ko din ni ọlọpaa mẹtadinlọgbọn tawọn eeyan bii arabinrin Afọlakẹ ti kọlu lati igba ti ajakalẹ arun COVID-19 yii ti bẹrẹ, ọpọlọpọ ninu wọn lo si ti di ero ileewosan ninu eyi ti wọn ko tii bọ di bi a ṣe n sọrọ yii. Laarin asiko ti a n sọrọ rẹ yii naa, ọkọ ọlọpaa bii marundinlogun ni awọn eeyan kan ti bajẹ, pẹlu ileeṣẹ ọẹọpaa meji ni Katsina ati Abia ni awọn eeyan kan ti dana sun. Ilumọọka adẹrinposonu lórí ayelujara, Oluwatoyin Bayegun, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ si Wòlíì Arole, tí ṣàlàyé pé ore-ọ̀fẹ́ àti àánú Ọlọ́run ló gbé òun sókè. O sọ nipa irinajo rẹ láti ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì ti òun ti bẹ̀rẹ̀ awada lórí ayelujara. Wòlíì Arole, lásìkò to ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé, isẹ awada sise tí gbé òun de ibi gíga, tí òun kò lérò pé òun leè de rí, tí òun ṣi tún mọ àwọn èèyàn ńlá-ńlá pẹ̀lú. "Mo ti lọ sí ilé aarẹ Nàìjíríà, Aso Rock ni ẹẹmeji, ìyàwó Buhari gan tí fun mi ni àmì ẹyẹ rí, mo sì máa ń lọ silu oyinbo loore koore, láti ipasẹ awada yìí náà ni." Wòlíì Arole ni "ọpọ ni kò fẹ́ kọ́kọ́ tẹ́wọ́ gba mi nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀, wọn ní èdè Yorùbá ni mo ń sọ àmọ́ nígbà tí kìí se àwọn ni Ọlọ́run, mo rí ọ̀nà àbáyọ." Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìpènijà tó ti là kọjá sẹ́yìn, Wòlíì Arole ni ọjọ́ kan wà tí wọn gba òun sì ẹgbẹ́ níbi ayẹyẹ kan torí pé òun kò tíì ní òkìkí nígbà náà àmọ́ òun dúpẹ́ fún ibi tí Ọlọ́run mú òun de lónìí. " Ẹ̀jẹ̀ mi ni Jésù, n kò sì tíì dé ibi tó ń mú mi lọ. Mo sì ń rọ àwọn èèyàn láti mase ro ara wọn pín, tàbí mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn wọn nitori ohun tí àwọn ènìyàn ba n sọ. Ọlọ́run ní kẹ gbé ọkàn yín lé, torí ohun ènìyàn kọ ni ohùn Ọlọ́run." O wa ṣàlàyé pé "Ọlọ́run ran iya mi sì mi. Òrìṣà ni ìyá mi, kii se ènìyàn. Mo fẹ́ràn ìyá mi gan-an ni, Kò sì sí Wòlíì Arole lai si ọwọ màmá mi nibẹ. Ó mọ mi denudenu, to sì fẹ́ràn mi tọkàntọkàn, tí ọkàn mi bá sì rẹ̀wẹ̀sì, ìyá mi lo máa ń tú mi nínú." Wòlíì Arole ni, ẹ̀bùn ni awada òun, tí ayé fi ń ko o jẹ, òun kii sì roo awada ti tẹ́lẹ̀, kí òun tó sọ síta, èyí tó máa ń jẹ ìtẹ́wọ́gbà lọdọ aráyé. Arole ni òun kò tíì ní ìyàwó nílé, àmọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ni yóò dárí òun lati darí isẹ àti ìdílé òun, lásìkò ti oun bá ní ìdílé. "O wu mi kì ń ṣe sinima àti show tèmi, kí n sì ni studio tèmi náà, Bẹ́ẹ̀ si ni èdè òyìnbó yọ lẹ́nu mi pẹ̀lú, bí mo ṣe leè ṣe awada ni ojúlówó èdè Yoruba náà ni awada tún dùn lẹ́nu mi ni èdè gẹ̀ẹ́sì, mo sì ni eto fún méjèèjì pẹ̀lú ni ọjọ́ iwájú." Arole wá rọ àwọn olólùfẹ́ rẹ láti jókòó sínú ilé wọn lásìkò igbele Coronavirus yìí, kí wọn sì mú gbogbo ìmọ̀ràn àti arọwa tí ìjọba ń pa fún wọn lọ nítorí ẹ̀mí kò ní ààrọ̀. Oluwadamilola Adeboye, tíì ṣe ọmọbìnrin gbajugbaja adẹrinposonu nnì, Gbenga Adeboye, tí sọ àwọn ìrírí tó sì rántí nípa bàbá rẹ̀ tó ti di olóògbé. Bẹẹ bá gbàgbé, Gbenga Adeboye lo jáde láyé ni ọgbọnjọ oṣù kẹrin ọdún 2003, èyí tó pé ọdún mẹtadinlogun lonii Ọjọ́bọ. Nígbà tó ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ láti sàmì ayajọ ìrántí ikú olóògbé náà, Oluwadamilola ni bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kéré pupọ nígbà tí bàbá òun kú, àmọ́ òun leè ṣe àpèjúwe rẹ bíi ẹni tó gbé aye ṣe rere. Oluwadamilola ni òun kò mọ ibi tí bàbá òun ti rí ẹ̀bùn tó ni àmọ́ ó fikùn pé, àwọn ẹ̀bùn rẹ náà kasiara, tó sì tún ya ní lẹ́nu pupọ. O ṣàlàyé pé nígbà tí bàbá òun wà láyé, ojoojumọ ni ile àwọn máa ń kùn, tí àwọn èèyàn máa ń wa, táwọn yóò sì gba àlejò, tí bàbá òun yóò sì máa ń ṣe awada pẹlu wọn, tí inú àwọn èèyàn yóò sì máa dùn, tí wọn kò sì ní fẹ́ kúrò nínú ilé àwọn. "Mo sì lee rántí pé Baba mi jẹ́ èèyàn rere, kò si ẹni ti kii se oore fún, kò si mọ bá ṣe ń kọ láti ṣe nkan fún èèyàn, tí onitọun bá nílò iranlọwọ." Nígbà miran ti bàbà mi bá dé sílè láti ibi tó ti lọ dá ẹrin posonu, tí a kò si ni oúnjẹ nílé, bí màmá mi bá béèrè pé owó tó mú bọ dà, yóò dáhùn pé òun ti pín owó náà fún àwọn tí ebi ń pá, tí yóò sì ní ká lọ mu gàárì, òun yóò fún wa lowo lọ́la láti fi ṣe irẹsi." Ọmọbìnrin Gbenga Adeboye náà fikùn pé, Baba òun ni ifẹ gbogbo ènìyàn bíi ọmọ àti àbúrò rẹ ni, ó sì tẹ bàbá òun lọrun pé ki awọn ẹbi rẹ mu gàárì kí àwọn ará ìta leè rí oúnjẹ jẹ, tàbí rí owó fún àwọn èèyàn. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí àwọn ẹbí fẹ́ máa fi ṣe irántí Gbenga Adeboye, Oluwadamilola ni "èmi àti màmá pẹ̀lú àwọn àbúrò mi ti pinnu láti máa ṣe atilẹyin fún àwọn osere tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde nilẹ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, ní kété tí ajakalẹ àrùn Coronavirus bá ti tan." O fikùn pé, àwọn yóò ṣe iranwọ fún àwọn osere tíátà lobinrin àti àwọn aláìní pẹ̀lú nítorí ohun tó máa ń mú inú bàbá òun dùn nìyẹn, èyí tíì ṣe fífún àwọn aláìní ni oúnjẹ.Bákan náà lo fikun pé ní ọjọ́ iwájú, tí àwọn bá tún ní erongba miran ti àwọn fẹ́ ṣe fún ìrántí Adeboye, àwọn yóò kéte síta. Ilumọọka olorin takasufe Davido ti kọ iwe ifẹ kan ṣọwọ si afẹsọna rẹ ati ọmọ wọn ni ọjọ ibi Chioma to n waye lọjọbọ Eyi wa loju opo Instagram rẹ. Mo ki obinrin to lagbara kulọ lara awọn ti mo mọ ku ọjọ ibi. Ka ni ko si ofin konile o gbele ni, awa mejeeji o ba ti jaye ori wa daada kaakiri igboro loni Iyawo mi tootọ, ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ yoo larinrin bi iwọ pẹlu ti ṣe mu ọpọlọpọ ayọ wọ inu aye mi. O ti le ni ọdun meji bayii ti Davido ati Chioma ti bẹrẹ irinajo ifẹ wọn ti Eleduwa si ti fi ọmọkunrin kan tawọn lọrẹ. Laipẹ yii ni Chioma bọ lọwọ arun Coronavirus lẹyin ọpọlọpọ ọjọ ti aisan naa fi daa wolẹ. Gbajugbaja akọrin takasufe ni, David Adeleke ti ọpọlọpọ mọ si Davido ti pariwo sita pe nnkan ko rẹrin lori titọju ọmọ ti oun ti iyawo rẹ Chioma bi fun latigba ti iya rẹ ti wa ni igbele iyasọtọ. Chioma, iyawo Davido ko arun Coronavirus eleyi ti ọkọ rẹ, Davido kede faye ni ọsẹ to kọja. Ninu ọrọ kan to fi sita loju opo twitter rẹ Davido lọgun pe iṣẹ l'abiyamọ n ṣe. Lẹyin ti ayẹwo fihan pe Chioma ti ko arun Coronavirus, igba meji ọtọọtọ ni Davido ni oun ti ṣe ayẹwo lati lee mọ boya oun ni arun naa tabi oun ko ni. Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alaaji Adegboyega Oyetọla ti ke gbajare sita pe awọn abọde lati orilẹede Côte d'Ivoire ni wọn jẹ ki ajakalẹ arun Coronavirus tubọ gogo sii ni ipinlẹ naa. Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ lori ẹrọ ibanisọrọ lẹyin ti ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun tun kede eeyan mẹsan miran pẹlu arun Korona ni ipinlẹ Ọṣun lọjọru, Gomina Oyetọla ṣalaye pe arun Korona ki ba ti burẹkẹ to bayii kani ijọba apapọ tete ti gbogbo ẹnuibode ni ki wọn si paṣẹ konileogbele fun gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria. Gomina Oyetọla ṣalaye siwaju sii pe, awọn ọmọ ipinlẹ naa ti wọn n ti orilẹede Côte d'Ivoire bọ wa sile ni wọn ko arun naa dani to fi di pe o tubọ peleke sii nipinlẹ naa. O wa rọ awsn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati fidimọle gẹgẹ bi aṣẹ ti ijọba pa lati lee wagbo dẹkun si wahala yii. Bakan naa ni o fi to wa leti pe lọna ati lee dẹkun ọwọja ebi ati inira lasiko aṣẹ konileogbele naa, ijọba oun ti gbe awọn igbesẹ ti yoo bu omi tu araalu lara bii sisanwo oṣu fun awọn oṣiṣẹ ki wọn to gbe aṣẹ naa kalẹ ati idasilẹ igbims majẹobajẹ kan lori ọna ati gbogun ti arun naa ati lati mu irọrun ba araalu lasiko ti wọn ba fi n baa wọ iyaaja. Ẹkunrẹrẹ wa ninu ohun ti a ka silẹ loke yii. Gbajugbaja akọrin takasufe, Divid Adeleke ti ọpọ eeyan mọ si Davido tun ti wẹ yan kainkain lọwọ arun coronavirus. Ọpọ ẹnu lo ti n kun Davido lẹyin ti iroyin jade pe ọpọ awọn eeyan to sun mọọ lo ti n ni arun yi lara. Ni ọjọ diẹ sẹyin ni Davido funrarẹ gbe iroyin jade pe iyawo oun, Chioma ti ko arun Coronavirus, bakan naa si ni gomina Seyi Makinde pẹlu kede pe oun pẹlu ti ni arun naa lẹyin ọjọ diẹ to gbalejo Davido ni ile ijọba nilu Ibadan. Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo twitter rẹ ni ọsan ọjọ Ọjọru, Davido ni oun ti tun ayẹwo arun Coronavirus ṣe o, ṣaka bayii si ni ara oun ya. Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde kede ni aṣalẹ ọjọ Aje pe oun ti ko arun Coronavirus ti o n ja kale-ka'ko bayii. O fi si oju opo twitter rẹ pe esi ayẹwo oun ti de ko si si ẹja n bakan kankan lori rẹ nitori ẹja lo ba de. Lẹyin eyi ni o ṣalaye pe gbogbo awọn to ti ni nnkan n ba oun ṣe laarin asiko ti oun fi lọ sibi ipade igbimọ ọrọ aje orilẹede Naijiria si ọjọ ti oun bẹrẹ igbele ni wọn ti n wa; koda iroyin kan tilẹ ss pe gbogbo awọn to baa da nnkan pọ laarin asiko naa, paapaa awọn kọmiṣọna atawọn amugbalẹgbẹ rẹ gbogbo ni wọn ti wa ni igbele bayii lati lee mọ boya awọn naa ko abi rara. Nibayii, BBC News Yoruba ṣe atupalẹ bi irinajo Gomina Seyi Makinde ṣe lọ laarin akoko naa ati awọn eeyan to ṣeeṣe ki wọn ti ko arun yii lati ara rẹ. Ẹ maa gbagbe pe eyi ko tumọ si pe gbogbo awọn eeyan to wa nibi eto wọnyii lo ti koo, ṣugbọn iwadi ati ayẹwo to gbọngbọn nikan lo lee fi idi eyi mulẹ. Fun apẹrẹ, gomina Makinde ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe asiko kan naa ni esi ayẹwo oun ati ti akọwe ijọba ipinlẹ naa, arabinrin Olubamiwo Adeosun de. Esi ti gomina lo jasi bẹẹni ti ti akọwe ijọba ipinlẹ naa si ja si bẹẹkọ. Idi ti awọn onimọ maa fi n ṣe ato irinajo ẹni to ba ni arun yii ni lati mọ ibi ti wọn lee wa awọn to lee ti koo lati ara wọn si. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-52117415 |
1entertainment
| Reminisce: Àwọn ọ̀dọ́ ló mọ ìtumọ̀ orin 'Problem'- Remilekun Abdulkalid Safaru, Alaga Baba Afusa | Remilekun Abdulkalid Safaru (Reminisce) sọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò ní òye nípa orin tí òun ń kọ. Ó ní òun kò sépè rárá nínú orin tí òun ń kọ sùgbọ́n àwọn ọ̀dọ́ nìkan ni ìtumọ̀ orin náà yé. Reminisce ní òun kìí gbé ìgbé ayé òpùrọ́ táa mọ̀ sí ‘fake life’. Ó ní gbogbo oore tí Ọlọrun se fún òun, ló tẹ́ òun lọ́rùn. | Reminisce: Àwọn ọ̀dọ́ ló mọ ìtumọ̀ orin 'Problem'- Remilekun Abdulkalid Safaru, Alaga Baba Afusa Remilekun Abdulkalid Safaru (Reminisce) sọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò ní òye nípa orin tí òun ń kọ. Ó ní òun kò sépè rárá nínú orin tí òun ń kọ sùgbọ́n àwọn ọ̀dọ́ nìkan ni ìtumọ̀ orin náà yé. Reminisce ní òun kìí gbé ìgbé ayé òpùrọ́ táa mọ̀ sí ‘fake life’. Ó ní gbogbo oore tí Ọlọrun se fún òun, ló tẹ́ òun lọ́rùn. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-43621773 |
4religion
| Makurdi Church theft: Àga oníke mẹ́wàá ní wọ́n kọ́kọ́ ni Joseph jí tó fi di èrò ẹ̀wọ̀n ní NASME Barracks ní Benue | Ọkùnrin ẹni ọdun marunlelogun kan, Joseph Ada ti NASME Barracks ni Makurdi ti foju bale ẹjọ majisireeti fun ẹsun ole jija, igbimọ iwa ọdaran. Ọlọpaa to wa nidi ẹjọ naa, Sajẹnti Regina Ishaya sọ fun ile ẹjọ pe, Arabinrin Myina Ifeyunwa lo mu ẹjọ naa wa si agọ ọlọpaa 'D' Division ni Markudi ni ogunjọ, oṣu kẹjọ, ọdun 2020. Olufisun ọ̀hún ni oun gba ipe lati ọdọ Ebenezer pe ẹnikan ti oun ko mọ ri jalẹkun wọ ile ijọsin Holy Ghost Sanctuary to je ti 'Penticostal' kan ni agbegbe Vita Foam, opopona oja tuntun ni Makurdi. O ni àwọn mu ẹni ti wọn fẹsun.kan naa pẹlu aga onike mẹwaa to jẹ ti ijọ naa. Sajẹnti Regina fi kun un pe, ěni ti wọn fẹsun kan naa fẹnu ara rẹ jẹwọ pe lootọ ni oun ji awọn aga naa amọ oun nikan kọ. O ka Usman Jafaru ati Terdoo Moses naa mọ wọn sugbọn ko si ẹni to mọ ibi ti wọn wa. Wọ́n tun ka awọn nkan miran ti wọn ji bi ẹrọ amunawa, faanu, ina lanta igbalode, ati aga onike mẹrinlelogoji ti owo gbogbo rẹ si to ẹgbẹrun lona ọọdunrun naira din diẹ, sugbọn iwadii si n tẹ siwaju. Ẹwẹ, ẹni a fẹsun kan naa ni oun ko jẹbi ẹsun ohun ti wọ́n fi kan oun tan. Adajọ Erdoo Ter to n dajọ ni majisireei naa wa ni ki wọn gba iduro pẹlu oniduro kan ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira. Wọn ti sun igbejọ naa si ọjọ kọkandinlọgbọn, ọsu kesan an, ọdun 2020. | Makurdi Church theft: Àga oníke mẹ́wàá ní wọ́n kọ́kọ́ ni Joseph jí tó fi di èrò ẹ̀wọ̀n ní NASME Barracks ní Benue Ọkùnrin ẹni ọdun marunlelogun kan, Joseph Ada ti NASME Barracks ni Makurdi ti foju bale ẹjọ majisireeti fun ẹsun ole jija, igbimọ iwa ọdaran. Ọlọpaa to wa nidi ẹjọ naa, Sajẹnti Regina Ishaya sọ fun ile ẹjọ pe, Arabinrin Myina Ifeyunwa lo mu ẹjọ naa wa si agọ ọlọpaa 'D' Division ni Markudi ni ogunjọ, oṣu kẹjọ, ọdun 2020. Olufisun ọ̀hún ni oun gba ipe lati ọdọ Ebenezer pe ẹnikan ti oun ko mọ ri jalẹkun wọ ile ijọsin Holy Ghost Sanctuary to je ti 'Penticostal' kan ni agbegbe Vita Foam, opopona oja tuntun ni Makurdi. O ni àwọn mu ẹni ti wọn fẹsun.kan naa pẹlu aga onike mẹwaa to jẹ ti ijọ naa. Sajẹnti Regina fi kun un pe, ěni ti wọn fẹsun kan naa fẹnu ara rẹ jẹwọ pe lootọ ni oun ji awọn aga naa amọ oun nikan kọ. O ka Usman Jafaru ati Terdoo Moses naa mọ wọn sugbọn ko si ẹni to mọ ibi ti wọn wa. Wọ́n tun ka awọn nkan miran ti wọn ji bi ẹrọ amunawa, faanu, ina lanta igbalode, ati aga onike mẹrinlelogoji ti owo gbogbo rẹ si to ẹgbẹrun lona ọọdunrun naira din diẹ, sugbọn iwadii si n tẹ siwaju. Ẹwẹ, ẹni a fẹsun kan naa ni oun ko jẹbi ẹsun ohun ti wọ́n fi kan oun tan. Adajọ Erdoo Ter to n dajọ ni majisireei naa wa ni ki wọn gba iduro pẹlu oniduro kan ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira. Wọn ti sun igbejọ naa si ọjọ kọkandinlọgbọn, ọsu kesan an, ọdun 2020. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-54040369 |
3politics
| Buhari Successor - Joe Igbokwe fèsì padà fáwọn àgbààgbà Ariwa tó ní ọ̀dọ́ àwọn ní ààrẹ ti ń bọ̀ ní 2023 | Eekan kan ninu ẹgbẹ oselu APC, Joe Igbokwe ti tutọ soke, fi oju gba a lori ikede kan ti awọn agbaagba lẹkun ariwa naijiria fisita lori ẹni ti yoo rọpo aarẹ Muhammadu Buhari. Ẹgbẹ awọn agbaagba ni Ariwa ilẹ yii lo kede ni Ọjọru pe ko si ohun to buru ninu ki aarẹ ti yoo rọpo Buhari tun wa lati ẹkun ariwa orilẹede yii. Baba Ahmed, tii se agbẹnusọ fun ẹgbẹ awọn agbaagba naa fikun pe ẹkun ariwa Naijiria ko tii setan lati gbe ipo agbara silẹ lọdun 2023. O wa gba awọn eeyan ti igbesẹ naa ko ba tẹ lọrun niyanju lati fi Naijiria fun awọn. Amọ nigba to n fesi lori ọrọ yii, Igbokwe ni ọrun yoo ya bọ silẹ, ti ohun buruku yoo si maa ja lu ohun buruku, ti eeyan miran lati apa ariwa Naijiria ba tun rọpo aarẹ Buhari. Igbokwe, ẹni to fi ọrọ naa lede loju opo ayelujara rẹ ni oun gbọ ohun ti Baba Ahmed sọ o amọ ọrun yoo bọ silẹ o. Ọpọ ọmọ Naijiria si lo ti dara pọ lati maa tako ohun ti ẹgbẹ awọn agbagba Arewa sọ naa, tawọn gomina ẹkun guusu Naijiria naa si ti fun lesi pada pe awada akọ lasan lo n se. O kere tan, awọn dokita onisegun oyinbo bii ọtalelọọdunrun o din meje (253) ni wọn ti fi orukọ silẹ laarin ọgọrun ọjọ lati sisẹ pẹlu ijọba ilẹ United Kingdom. Gẹgẹ bi oju opo itakun agbaye fun ajọ to n se akoso isẹ isegun nilẹ UK, to maa n fawọn dokita niwe asẹ lati sisẹ ti kede rẹ. Laarin ọjọ Kẹwa osu Kẹfa si ogunjọ osu Kẹsan ọdun 2021, dokita ọmọ Naijiria bii ọtalelọọdunrun o din meje lo ti gba iwe asẹ lati sisẹ nilẹ naa. Bakan naa, gẹgẹ bi iwe Punch ti salaye, laarin osu keje ọdun 2020 si osu Kẹsan ọdun 2021, awọn dokita to to ọtalelẹgbẹrin ati meji (862) lo ti gba iwe asẹ lati sisẹ ni UK lai naani arun Coronavirus to gbilẹ nibẹ nigba naa. Lọwọ lọwọ bayii, dokita bii ẹgbẹrun mẹjọ ati ọrinlelẹẹdẹgbẹrin o din mẹta (8,737) ti wọn gba idanilẹkọ nipa isẹ dokita lorilẹede Naijiria, lo ti n sisẹ nilẹ UK. Nigba to n ba iwe iroyin naa sọrọ, igbakeji aarẹ ẹgbẹ awọn dokita to n gba imọ kun imọ ni Naijiria, Julian Ojebo ni o seese ki alekun ba bi awọn dokita se n lọ soke okun laarin ọsẹ melo kan si. Ojebo ni ti ijọba ko ba san owo osu ati ajẹmọnu to yẹ fawọn onisegun oyinbo naa, o seese ki iye awọn ti yoo gba orilẹede Saudi Arabia lọ gan ju ti UK lọ. O fikun pe o se ni laanu pe ijọba kuna lati wa ojutu si ohun tawọn dokita naa n beere fun lati ọjọ Kinni osu Kẹjọ ọdun 2021 ti wọn ti bẹrẹ iyansẹlodi. | Buhari Successor - Joe Igbokwe fèsì padà fáwọn àgbààgbà Ariwa tó ní ọ̀dọ́ àwọn ní ààrẹ ti ń bọ̀ ní 2023 Eekan kan ninu ẹgbẹ oselu APC, Joe Igbokwe ti tutọ soke, fi oju gba a lori ikede kan ti awọn agbaagba lẹkun ariwa naijiria fisita lori ẹni ti yoo rọpo aarẹ Muhammadu Buhari. Ẹgbẹ awọn agbaagba ni Ariwa ilẹ yii lo kede ni Ọjọru pe ko si ohun to buru ninu ki aarẹ ti yoo rọpo Buhari tun wa lati ẹkun ariwa orilẹede yii. Baba Ahmed, tii se agbẹnusọ fun ẹgbẹ awọn agbaagba naa fikun pe ẹkun ariwa Naijiria ko tii setan lati gbe ipo agbara silẹ lọdun 2023. O wa gba awọn eeyan ti igbesẹ naa ko ba tẹ lọrun niyanju lati fi Naijiria fun awọn. Amọ nigba to n fesi lori ọrọ yii, Igbokwe ni ọrun yoo ya bọ silẹ, ti ohun buruku yoo si maa ja lu ohun buruku, ti eeyan miran lati apa ariwa Naijiria ba tun rọpo aarẹ Buhari. Igbokwe, ẹni to fi ọrọ naa lede loju opo ayelujara rẹ ni oun gbọ ohun ti Baba Ahmed sọ o amọ ọrun yoo bọ silẹ o. Ọpọ ọmọ Naijiria si lo ti dara pọ lati maa tako ohun ti ẹgbẹ awọn agbagba Arewa sọ naa, tawọn gomina ẹkun guusu Naijiria naa si ti fun lesi pada pe awada akọ lasan lo n se. O kere tan, awọn dokita onisegun oyinbo bii ọtalelọọdunrun o din meje (253) ni wọn ti fi orukọ silẹ laarin ọgọrun ọjọ lati sisẹ pẹlu ijọba ilẹ United Kingdom. Gẹgẹ bi oju opo itakun agbaye fun ajọ to n se akoso isẹ isegun nilẹ UK, to maa n fawọn dokita niwe asẹ lati sisẹ ti kede rẹ. Laarin ọjọ Kẹwa osu Kẹfa si ogunjọ osu Kẹsan ọdun 2021, dokita ọmọ Naijiria bii ọtalelọọdunrun o din meje lo ti gba iwe asẹ lati sisẹ nilẹ naa. Bakan naa, gẹgẹ bi iwe Punch ti salaye, laarin osu keje ọdun 2020 si osu Kẹsan ọdun 2021, awọn dokita to to ọtalelẹgbẹrin ati meji (862) lo ti gba iwe asẹ lati sisẹ ni UK lai naani arun Coronavirus to gbilẹ nibẹ nigba naa. Lọwọ lọwọ bayii, dokita bii ẹgbẹrun mẹjọ ati ọrinlelẹẹdẹgbẹrin o din mẹta (8,737) ti wọn gba idanilẹkọ nipa isẹ dokita lorilẹede Naijiria, lo ti n sisẹ nilẹ UK. Nigba to n ba iwe iroyin naa sọrọ, igbakeji aarẹ ẹgbẹ awọn dokita to n gba imọ kun imọ ni Naijiria, Julian Ojebo ni o seese ki alekun ba bi awọn dokita se n lọ soke okun laarin ọsẹ melo kan si. Ojebo ni ti ijọba ko ba san owo osu ati ajẹmọnu to yẹ fawọn onisegun oyinbo naa, o seese ki iye awọn ti yoo gba orilẹede Saudi Arabia lọ gan ju ti UK lọ. O fikun pe o se ni laanu pe ijọba kuna lati wa ojutu si ohun tawọn dokita naa n beere fun lati ọjọ Kinni osu Kẹjọ ọdun 2021 ti wọn ti bẹrẹ iyansẹlodi. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58648164 |
3politics
| Àdúrà lásán ni mo gbà fún Peter Obi, mi ò ní agbára láti fa ọwọ́ rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ààre títún - Olubadan | Agbẹnusọ fun Olubadan ti ilẹ Ibadan Oladele Ogunsola ni Ọba Sẹnetọ Lekan Balogun, Alli Okunmade keji ti ṣalaye awuyewuye lori fọnran ti o wa lori ayelujara nipa bi Kabiyesi Olubadan ti Ibadan ṣe n gbadura fun oludije ṣipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party gẹgẹ bii eke lati tan awọn ẹniyan jẹ. A o ranti pe oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ Labour Party (LP) lo dari ikọ ipolongo rẹ lati ṣe abẹwo si Olubadan ni ọjọ Abameta to kọja yii ti awọn Oloye miran si darapọ mọ ọ lati gba alejo rẹ ni aafin Olubadan to wa ni Alarere nilu Ibadan. Awọn Oloye ti o wa ni ijoko nigba ti Peter Obi wa ni, Otun Balogun ti Ibadan, Osi, Ashipa ati Ekerin Olubadan, Oloye agba Owolabi Olakulehin, Tajudeen Ajibola, Lateef Gbadamosi Adebimpe, Kola Adegbola, Eddy Oyewole ati Hamidu Ajibade. Nigba ti Oloye Ajibola fesi si ọrọ ipolongo ti Peter Obi ba wa, ti Oloye Oyewole si gbadura fun un lori erongba rẹ. Oladele Olusola ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu ile BBC YORUBA ni adura nikan ni awọn oloye ṣe tí Olubadan funra rẹ kọ si sọrọ rara ninu fọnran ti wọn gbe sita. O ni aṣa aafin ni lati gbadura fun gbogbo awọn ti wọn ba wa pe ki erongba wọn ko ṣẹ. O fi kun un pe Kabiyesi Olubadan ko fa ọwọ ẹni kankan soke nitori Peter Obi nikan kọ ni oludije ṣipo aarẹ ti yoo wa si aafin. Olusola ni erongba awọn ololufẹ Peter Obi ni wọn gbe sori awọn ẹrọ ayelujara ti wọn si fi aafin olubadan ṣe ogbufo fun nitori ilẹkun aafin sii silẹ gbayawu fun gbogbo awọn oloṣelu ati gbogbo ara ilu. Agbẹnusọ fun Olubadan ni ṣaaju ki ẹto ipolongo ṣipo aarẹ to bẹrẹ ni awọn oludije ti n wa ki Kabiyesi l'aafin, ninu eyi ti Rabiu Kwankwaso ati awọn oloṣelu miiran naa ti wa ki Olubadan. Oni nnkan awada ni ki Olubadan gbe ọwọ ẹnikan soke ni gbangba nitori Ọba gbogbogbo ni Olubadan jẹ kii sii ṣẹ oloṣelu. | Àdúrà lásán ni mo gbà fún Peter Obi, mi ò ní agbára láti fa ọwọ́ rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ààre títún - Olubadan Agbẹnusọ fun Olubadan ti ilẹ Ibadan Oladele Ogunsola ni Ọba Sẹnetọ Lekan Balogun, Alli Okunmade keji ti ṣalaye awuyewuye lori fọnran ti o wa lori ayelujara nipa bi Kabiyesi Olubadan ti Ibadan ṣe n gbadura fun oludije ṣipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party gẹgẹ bii eke lati tan awọn ẹniyan jẹ. A o ranti pe oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ Labour Party (LP) lo dari ikọ ipolongo rẹ lati ṣe abẹwo si Olubadan ni ọjọ Abameta to kọja yii ti awọn Oloye miran si darapọ mọ ọ lati gba alejo rẹ ni aafin Olubadan to wa ni Alarere nilu Ibadan. Awọn Oloye ti o wa ni ijoko nigba ti Peter Obi wa ni, Otun Balogun ti Ibadan, Osi, Ashipa ati Ekerin Olubadan, Oloye agba Owolabi Olakulehin, Tajudeen Ajibola, Lateef Gbadamosi Adebimpe, Kola Adegbola, Eddy Oyewole ati Hamidu Ajibade. Nigba ti Oloye Ajibola fesi si ọrọ ipolongo ti Peter Obi ba wa, ti Oloye Oyewole si gbadura fun un lori erongba rẹ. Oladele Olusola ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu ile BBC YORUBA ni adura nikan ni awọn oloye ṣe tí Olubadan funra rẹ kọ si sọrọ rara ninu fọnran ti wọn gbe sita. O ni aṣa aafin ni lati gbadura fun gbogbo awọn ti wọn ba wa pe ki erongba wọn ko ṣẹ. O fi kun un pe Kabiyesi Olubadan ko fa ọwọ ẹni kankan soke nitori Peter Obi nikan kọ ni oludije ṣipo aarẹ ti yoo wa si aafin. Olusola ni erongba awọn ololufẹ Peter Obi ni wọn gbe sori awọn ẹrọ ayelujara ti wọn si fi aafin olubadan ṣe ogbufo fun nitori ilẹkun aafin sii silẹ gbayawu fun gbogbo awọn oloṣelu ati gbogbo ara ilu. Agbẹnusọ fun Olubadan ni ṣaaju ki ẹto ipolongo ṣipo aarẹ to bẹrẹ ni awọn oludije ti n wa ki Kabiyesi l'aafin, ninu eyi ti Rabiu Kwankwaso ati awọn oloṣelu miiran naa ti wa ki Olubadan. Oni nnkan awada ni ki Olubadan gbe ọwọ ẹnikan soke ni gbangba nitori Ọba gbogbogbo ni Olubadan jẹ kii sii ṣẹ oloṣelu. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cd12lzzz8dro |
2health
| Covid-19 Vaccine: Obìnrin kán sọ ìdí tí kò fi gba àjẹ́rẹ́ àjẹsára, tó sì pàdánù ìṣẹ́ rẹ̀ | Ni orilẹede Naijiria, ọpọ eeyan ni ẹru n ba lati gba abẹrẹ ajẹsara to n gbogun ti aisan Coronavirus, ti awọn eeyan kan si n fi aake kọri pe awọn ko ni gba abẹrẹ naa. Ijọba apapọ gan ti kede pe abẹrẹ ajẹsara yii ti di ọranyan fun awọn osisẹ ọba atawọn eeyan to fẹ wọnu awọn ileesẹ ijọba. Gbogbo wọn si lo gbọdọ fi iwe ẹri han pe wọn ti gba abẹrẹ naa tabi se ayẹwo pe awọn ko ni arun Covid-19, ki wọn to le wọnu ọọfisi ijọba. Ọpọ ariwisi ati ifẹhonu han lori ayelujara si lo tẹle ikede naa, tawọn araalu si ni igbesẹ naa tako ẹtọ ọmọniyan lati se ohun to ba fẹ. Amọ bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan mu iwa yii jẹ ni Naijiria, ti ko si si nnkan kan to ti ẹyin rẹ yọ, amọ obinrin kan ree nilẹ Amẹrika, ti ọrọ naa yiwọ fun. Danielle Thornton ati ọkọ rẹ ni wọn pinnu pe awọn ko ni gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 naa, ti wọn si fi ọwọ lẹran maa woye ohun ti yoo tẹyin igbesẹ naa yọ. Koda, o han gbangba si wọn pe o seese ki awọn padanu isẹ oojọ awọn, ti awọn ko ba gba abẹrẹ naa. Gẹgẹ bi Danielle ti wi, oun ati ọkọ oun jiroro pupọ lori igbesẹ gbigba abẹrẹ ajẹsara naa, ti awọn si fi ẹnu ko pe ominira awọn se iyebiye ju owo osu lọ. Obinrin yii si lo jẹ ọkan lara ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan ni Amẹrika to fara mọ pe ki awọn sọ isẹ nu ju ki awọn gba abẹrẹ Covid-19 lọ. Iru awọn eeyan ti ko gba abẹrẹ yii si ni wọn kere niye bii ida mẹẹdọgbọn ninu ọgọrun eeyan to wa ni orilẹede Amẹrika. The Banki Citigroup ti Danielle ti n sisẹ, ida kan osisẹ wọn lo kọ lati gba abẹrẹ naa, ti awọn yoku si ti gba a eyi ti wọn ni yoo dena ewu pupọ. Ni osu January yii, ile ẹjọ to ga julọ nilẹ Amẹrika wọgile ofin kan ti aarẹ Joe Biden gbe wa siwaju rẹ. Biden ni oun n fẹ ki o kere tan, ọgọrun eeyan nibi isẹ kan, ti gba abẹrẹ ajẹsara naa, tabi maa lo ibomu loore koore tabi maa se idanwo ayẹwo Covid-19 lọsọọsẹ pẹlu owo apo wọn. Gẹgẹ bi Danielle ti wi, oun kii se oloselu, bẹẹ ni oun ko tako igbesẹ gbigba abẹrẹ ajẹsara naa nitori oun ti gba tẹlẹ nigba ti abẹrẹ naa sẹsẹ de. Amọ o ni oun ni ẹtọ lati yan oun ti oun n fẹ, ti igbesẹ oun lati padanu isẹ oun yoo si nipa nla lori mọlẹbi oun. | Covid-19 Vaccine: Obìnrin kán sọ ìdí tí kò fi gba àjẹ́rẹ́ àjẹsára, tó sì pàdánù ìṣẹ́ rẹ̀ Ni orilẹede Naijiria, ọpọ eeyan ni ẹru n ba lati gba abẹrẹ ajẹsara to n gbogun ti aisan Coronavirus, ti awọn eeyan kan si n fi aake kọri pe awọn ko ni gba abẹrẹ naa. Ijọba apapọ gan ti kede pe abẹrẹ ajẹsara yii ti di ọranyan fun awọn osisẹ ọba atawọn eeyan to fẹ wọnu awọn ileesẹ ijọba. Gbogbo wọn si lo gbọdọ fi iwe ẹri han pe wọn ti gba abẹrẹ naa tabi se ayẹwo pe awọn ko ni arun Covid-19, ki wọn to le wọnu ọọfisi ijọba. Ọpọ ariwisi ati ifẹhonu han lori ayelujara si lo tẹle ikede naa, tawọn araalu si ni igbesẹ naa tako ẹtọ ọmọniyan lati se ohun to ba fẹ. Amọ bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan mu iwa yii jẹ ni Naijiria, ti ko si si nnkan kan to ti ẹyin rẹ yọ, amọ obinrin kan ree nilẹ Amẹrika, ti ọrọ naa yiwọ fun. Danielle Thornton ati ọkọ rẹ ni wọn pinnu pe awọn ko ni gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 naa, ti wọn si fi ọwọ lẹran maa woye ohun ti yoo tẹyin igbesẹ naa yọ. Koda, o han gbangba si wọn pe o seese ki awọn padanu isẹ oojọ awọn, ti awọn ko ba gba abẹrẹ naa. Gẹgẹ bi Danielle ti wi, oun ati ọkọ oun jiroro pupọ lori igbesẹ gbigba abẹrẹ ajẹsara naa, ti awọn si fi ẹnu ko pe ominira awọn se iyebiye ju owo osu lọ. Obinrin yii si lo jẹ ọkan lara ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan ni Amẹrika to fara mọ pe ki awọn sọ isẹ nu ju ki awọn gba abẹrẹ Covid-19 lọ. Iru awọn eeyan ti ko gba abẹrẹ yii si ni wọn kere niye bii ida mẹẹdọgbọn ninu ọgọrun eeyan to wa ni orilẹede Amẹrika. The Banki Citigroup ti Danielle ti n sisẹ, ida kan osisẹ wọn lo kọ lati gba abẹrẹ naa, ti awọn yoku si ti gba a eyi ti wọn ni yoo dena ewu pupọ. Ni osu January yii, ile ẹjọ to ga julọ nilẹ Amẹrika wọgile ofin kan ti aarẹ Joe Biden gbe wa siwaju rẹ. Biden ni oun n fẹ ki o kere tan, ọgọrun eeyan nibi isẹ kan, ti gba abẹrẹ ajẹsara naa, tabi maa lo ibomu loore koore tabi maa se idanwo ayẹwo Covid-19 lọsọọsẹ pẹlu owo apo wọn. Gẹgẹ bi Danielle ti wi, oun kii se oloselu, bẹẹ ni oun ko tako igbesẹ gbigba abẹrẹ ajẹsara naa nitori oun ti gba tẹlẹ nigba ti abẹrẹ naa sẹsẹ de. Amọ o ni oun ni ẹtọ lati yan oun ti oun n fẹ, ti igbesẹ oun lati padanu isẹ oun yoo si nipa nla lori mọlẹbi oun. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60112178 |
1entertainment
| Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó | Se ẹ ranti ere onijo “Alfa Sule, That is to say, o ti gan pa, awo jiginni? Ni bii ọdun melo kan sẹyin nigba ti itakun agbaye ko tii de, ere onijo yii, ti oloyinbo n pe ni “Dance Drama” si lo gbalẹ kan. Bo se n waye lawọn ile ẹkọ, paapaa lasiko ayẹyẹ opin ọdun, naa lo n waye lawọn ile ijọsin gbogbo, paapaa lati pe ọkan awọn eeyan pada si ọdọ Ọlọrun. Wo àwọn ibi mẹ́rin tí ènìyàn kò le fi ẹsẹ̀ tẹ̀ láyé Ẹgbẹ́ Shiite kọ̀wé pe àwọn pásítọ̀ láti darapọ̀ mọ́ ìwọ́de tí wọ́n fẹ́ ẹ̀ ṣe lọ́jọ́ Ẹtì Ọ̀rúnmìlà ni ó kọ́kọ́ lo 'Google' láàgbáyé-Ọ̀ọ̀ni Ìlẹ̀ ifẹ̀ Èyí ni 'àbẹ́tẹ̀' àgbo ìgbàlódé Ṣe ọmọ táa bí "fine" ni ìyàwó mi ń bèrè, mo tún ń pa á lẹ́rìín kó má mọ̀ pé ọmọ ti kú - Woli Agba Ayo Ajewole Taaooma tọrọ aforíjìn pé ó bá ìgbákejì ààrẹ ṣèpàdé, èsì Mr Macaroni àtàwọn ọdọ́ rèé Òṣìṣẹ́ ológun Navy ni mí àmọ́ àwàdà ayélujára ló sọ mí di olókìkí - Cute Abiola Ìyá mi máa ń ni mo parọ́ mọ́ àwọn pẹ̀lú adúrú ìgbátí tí mo máa ń lò nínú "skit"- Taaooma Apokagi Taaooma tọrọ aforíjìn pé ó bá ìgbákejì ààrẹ ṣèpàdé, èsì Mr Macaroni àtàwọn ọdọ́ rèé Oshisko twins, àwọn 'ìbejì' tó ń dẹ́rìn ín p'òṣónú Àfìgbà tóò dúró ká jọ gbé orin tuntun wa pẹ̀lú Alhaji Mustapha Abiola jáde - Ẹnìkejì Tope Ajogbajesu Kí ló fàá tí Dele máa ń ṣe àìgbọ́ràn sí Wòlíì? Ọpọ ọdọ si lo maa n kọrin to jade lati ara ere alujo naa kaakiri nigba naa bii ‘That is to say, o ti gan pa, eyi to di asa lasiko naa. Amọ pupọ eeyan ni ko mọ ọkunrin to ko asa ere onijo naa de saarin wa nilẹ Yoruba, eyi to gbalẹ kan nigba naa. Oluwa rẹ ni Oluwafemi Ajewole, ti gbogbo eeyan tun mọ si Alfa Sule. Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori bo se bẹrẹ ere onijo naa, Adewole ni lara akẹkọ ọmọ kekere kan ni imisi naa ti wa. O ni ọmọ naa ni oun maa n kọ ni imọ isiro amọ ti ayọkuro ati aropọ ko tete ye ọmọ naa. Idi si ree ti oun fi sọ ilana ayọkuro ati aropọ ninu isiro di orin kikọ, orin yii si ni ọmọde naa maa n ranti lati se amulo ilana ayọkuro ati aropọ ti oun ba gbe fun. “Bi mo se bẹrẹ ere onijo naa ree amọ mo tun pa a ti lati lọkọ ẹkọ imọ ẹrọ ni Poly. Sugbọn ọrọ kan ti akẹẹgbẹ mi ni kilaasi sọ nigba ta n reti olukọ wa fun wakati mẹta, ni Ọlọrun fi si mi leti lati pada sidi ere onijo naa. Akẹẹgbẹ mi naa beere pe ‘se gbogbo wa la fi imọ ẹrọ ta n kọ yii jẹun ni?’ Ibeere naa gun mi lẹmi, mo gbadura si, ti Ọlọrun si sọ fun mi pe oun ti fi ọna ti maa gba han mi. Lati igba naa si ni mo ti pada sidi ere alujo naa, to si di gbajugbaja ati itẹwọgba.” Alfa Sule, nigba to n salaye ọpọ ipenija to koju rẹ nidi ilana ere onijo to mu pọn naa, o salaye pe oju ri pupọ. O ni awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹẹdogun lọ ni oun ko jọ lati sere naa, ti oye isẹ naa ko si tete ye wọn nibẹrẹ. Bakan naa lo ni oun nikan ni oun maa n sọ gbogbo ọrọ to ba wa ninu ere onijo naa boya ni oun ọkunrin ni tabi ti obinrin. Amọ iyawo oun lo n fọ oun obinrin bayii nigba ti oun gbe iyawo. Pabambari ipenija to ni o tun koju oun ni ti awọn Kristiẹni to wa nijọ alasọ funfun ati awọn Musulumi ti wọn ro pe awọn ni oun fi ere onijo gbogun ti. | Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó Se ẹ ranti ere onijo “Alfa Sule, That is to say, o ti gan pa, awo jiginni? Ni bii ọdun melo kan sẹyin nigba ti itakun agbaye ko tii de, ere onijo yii, ti oloyinbo n pe ni “Dance Drama” si lo gbalẹ kan. Bo se n waye lawọn ile ẹkọ, paapaa lasiko ayẹyẹ opin ọdun, naa lo n waye lawọn ile ijọsin gbogbo, paapaa lati pe ọkan awọn eeyan pada si ọdọ Ọlọrun. Wo àwọn ibi mẹ́rin tí ènìyàn kò le fi ẹsẹ̀ tẹ̀ láyé Ẹgbẹ́ Shiite kọ̀wé pe àwọn pásítọ̀ láti darapọ̀ mọ́ ìwọ́de tí wọ́n fẹ́ ẹ̀ ṣe lọ́jọ́ Ẹtì Ọ̀rúnmìlà ni ó kọ́kọ́ lo 'Google' láàgbáyé-Ọ̀ọ̀ni Ìlẹ̀ ifẹ̀ Èyí ni 'àbẹ́tẹ̀' àgbo ìgbàlódé Ṣe ọmọ táa bí "fine" ni ìyàwó mi ń bèrè, mo tún ń pa á lẹ́rìín kó má mọ̀ pé ọmọ ti kú - Woli Agba Ayo Ajewole Taaooma tọrọ aforíjìn pé ó bá ìgbákejì ààrẹ ṣèpàdé, èsì Mr Macaroni àtàwọn ọdọ́ rèé Òṣìṣẹ́ ológun Navy ni mí àmọ́ àwàdà ayélujára ló sọ mí di olókìkí - Cute Abiola Ìyá mi máa ń ni mo parọ́ mọ́ àwọn pẹ̀lú adúrú ìgbátí tí mo máa ń lò nínú "skit"- Taaooma Apokagi Taaooma tọrọ aforíjìn pé ó bá ìgbákejì ààrẹ ṣèpàdé, èsì Mr Macaroni àtàwọn ọdọ́ rèé Oshisko twins, àwọn 'ìbejì' tó ń dẹ́rìn ín p'òṣónú Àfìgbà tóò dúró ká jọ gbé orin tuntun wa pẹ̀lú Alhaji Mustapha Abiola jáde - Ẹnìkejì Tope Ajogbajesu Kí ló fàá tí Dele máa ń ṣe àìgbọ́ràn sí Wòlíì? Ọpọ ọdọ si lo maa n kọrin to jade lati ara ere alujo naa kaakiri nigba naa bii ‘That is to say, o ti gan pa, eyi to di asa lasiko naa. Amọ pupọ eeyan ni ko mọ ọkunrin to ko asa ere onijo naa de saarin wa nilẹ Yoruba, eyi to gbalẹ kan nigba naa. Oluwa rẹ ni Oluwafemi Ajewole, ti gbogbo eeyan tun mọ si Alfa Sule. Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori bo se bẹrẹ ere onijo naa, Adewole ni lara akẹkọ ọmọ kekere kan ni imisi naa ti wa. O ni ọmọ naa ni oun maa n kọ ni imọ isiro amọ ti ayọkuro ati aropọ ko tete ye ọmọ naa. Idi si ree ti oun fi sọ ilana ayọkuro ati aropọ ninu isiro di orin kikọ, orin yii si ni ọmọde naa maa n ranti lati se amulo ilana ayọkuro ati aropọ ti oun ba gbe fun. “Bi mo se bẹrẹ ere onijo naa ree amọ mo tun pa a ti lati lọkọ ẹkọ imọ ẹrọ ni Poly. Sugbọn ọrọ kan ti akẹẹgbẹ mi ni kilaasi sọ nigba ta n reti olukọ wa fun wakati mẹta, ni Ọlọrun fi si mi leti lati pada sidi ere onijo naa. Akẹẹgbẹ mi naa beere pe ‘se gbogbo wa la fi imọ ẹrọ ta n kọ yii jẹun ni?’ Ibeere naa gun mi lẹmi, mo gbadura si, ti Ọlọrun si sọ fun mi pe oun ti fi ọna ti maa gba han mi. Lati igba naa si ni mo ti pada sidi ere alujo naa, to si di gbajugbaja ati itẹwọgba.” Alfa Sule, nigba to n salaye ọpọ ipenija to koju rẹ nidi ilana ere onijo to mu pọn naa, o salaye pe oju ri pupọ. O ni awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹẹdogun lọ ni oun ko jọ lati sere naa, ti oye isẹ naa ko si tete ye wọn nibẹrẹ. Bakan naa lo ni oun nikan ni oun maa n sọ gbogbo ọrọ to ba wa ninu ere onijo naa boya ni oun ọkunrin ni tabi ti obinrin. Amọ iyawo oun lo n fọ oun obinrin bayii nigba ti oun gbe iyawo. Pabambari ipenija to ni o tun koju oun ni ti awọn Kristiẹni to wa nijọ alasọ funfun ati awọn Musulumi ti wọn ro pe awọn ni oun fi ere onijo gbogun ti. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61126061 |
5sports
| Arsenal vs Chelsea: Arteta pariwo lẹ́yìn tí Chelsea lu Arsenal bíi bàrà mọ́lé | Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Mikel Arteta ti sọ pe iṣoro nla lo n koju Arsenal bayii. Arteta sọrọ yii fawọn akọroyin lẹyin ti Chelsea poko iya fun Arsenal tan pẹlu ami ayo meji sodo nile wọn ni papa iṣere Emirates niluu London lọjọ Aiku. Arteta ni ohun to n ṣe Arsenal buru debi wi pe ko si ẹni to ye. Arsenal ti kọkọ fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti wọn gba pẹlu ikọ agbabọọlu Brentford to ṣẹṣẹ goke wa si idije Premier League fun igba akọkọ lẹyin ọdun mẹrinlelaadọrin. Ami ayo meji si odo ti Chelsea ti da ṣeria fun Arsenal mọle naa ni Brentford naa fi ṣagba wọn. Eyi ni igba akọkọ ti Arsenal yoo fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ meji akọkọ ti wọn gba ni ibẹrẹ saa bọọlu EPL lai le gba ayo kankan sawọn. Ko ṣẹlẹ r tẹlẹ! Arteta sọ fun BBC pe awọn agbabọọlu oun kan lugbadi arun covid-19 nigba tawọn mii fi ẹsẹ ṣeeṣe. ''N ko ro pe iru nkan bayii ti ṣẹlẹ ri si Arsenal ninu itan ẹgbẹ agbabọọlu yii. Ṣugbọn a ni lati ṣe bi akin, ki a si koju iṣoro to n doju kọ wa. Kii ṣe inu oṣu yii ni a maa mọ awọn ikọ agbabọọlu ti yoo pegede, ohun to buru ni pe ki a sọ ireti nu. Ṣugbọn a ko ni sọ ireti nu, a o tubọ gbiyanju sii ni. Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ meji ti o ti waye ni saa bọọlu tuntun EPL yii, Arsenal lo wa ni ipo to kangun si eleyi ko kẹyin lori tabili EPL. Arteta ta Pàù! Lukaku lagi mọ́ Arsenal lórí láti gbayì fún Chelsea Gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lo ti korin bọnu, ti wọn si n fi ẹgbẹ agbaọọlu arsenal ṣe ẹlẹya lẹyin ti wọmn ko wọn ni bulala meji si odo Bi o ti lẹ jẹ pe igba meji pere ni Arsenal ti gba bọọlu bi saa premiere liigi to bẹrẹ yìí, sibẹ wọn ko ti gba pọnti kankan, bakan naa ni wọn sọ oore- ọfẹ lati gba bọọlu sawọn nu ni ẹẹmẹrin. Awọn ọmọ ikọ agbabọọlu Chelsae ti fakọyọ ni ẹẹmeji ti wọn ti dije ni saayii, ti wọn si ti jẹ nigba marun, koda, Romelu Lukaku ti wọn ṣẹsẹ kowo le lori se gudugujdu meje yaya mẹfa ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ to ti waye yii. Lilọ bibọ Lukaku yii gan lo dabi orififọ fun ikọ agbaọọlu Arsenal James pẹlu naa ko gbẹyin bi oun ati Mason ṣe jọ n ran ara wọn lọwọ lati goolu keji Diẹ lo ku ki Lukaku tun jẹ goolu kẹta sùgbọn ṣe lo fi ori gba bọọlu na lu irin oju ile. O jọ bi ẹni pe Ben White to yẹ ko dile mu lọwọ ẹyin fun Arsenal ti ko si nibẹ nitori aarun Covid-19 to de mọọlẹ o jẹ nnkan to n yọ Arsenal lẹnu . Nnkan ti oju Arsenal ti ri laarin ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn ti gba ni saa yii ti fẹ buru ju ti saa liigi to kọja lọ. Igba kẹta ree, ti ikọ agbaọọlu Arsenal yoo fidirẹmi ninu idije meji ni tẹlẹntẹle ni saa liigi tuntun Ibeere ti ọpọ n bere ni pe, ṣe Arteta ko duro gba sabuke lọwọ Pep guardiola to ti kọsẹ ni? | Arsenal vs Chelsea: Arteta pariwo lẹ́yìn tí Chelsea lu Arsenal bíi bàrà mọ́lé Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Mikel Arteta ti sọ pe iṣoro nla lo n koju Arsenal bayii. Arteta sọrọ yii fawọn akọroyin lẹyin ti Chelsea poko iya fun Arsenal tan pẹlu ami ayo meji sodo nile wọn ni papa iṣere Emirates niluu London lọjọ Aiku. Arteta ni ohun to n ṣe Arsenal buru debi wi pe ko si ẹni to ye. Arsenal ti kọkọ fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti wọn gba pẹlu ikọ agbabọọlu Brentford to ṣẹṣẹ goke wa si idije Premier League fun igba akọkọ lẹyin ọdun mẹrinlelaadọrin. Ami ayo meji si odo ti Chelsea ti da ṣeria fun Arsenal mọle naa ni Brentford naa fi ṣagba wọn. Eyi ni igba akọkọ ti Arsenal yoo fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ meji akọkọ ti wọn gba ni ibẹrẹ saa bọọlu EPL lai le gba ayo kankan sawọn. Ko ṣẹlẹ r tẹlẹ! Arteta sọ fun BBC pe awọn agbabọọlu oun kan lugbadi arun covid-19 nigba tawọn mii fi ẹsẹ ṣeeṣe. ''N ko ro pe iru nkan bayii ti ṣẹlẹ ri si Arsenal ninu itan ẹgbẹ agbabọọlu yii. Ṣugbọn a ni lati ṣe bi akin, ki a si koju iṣoro to n doju kọ wa. Kii ṣe inu oṣu yii ni a maa mọ awọn ikọ agbabọọlu ti yoo pegede, ohun to buru ni pe ki a sọ ireti nu. Ṣugbọn a ko ni sọ ireti nu, a o tubọ gbiyanju sii ni. Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ meji ti o ti waye ni saa bọọlu tuntun EPL yii, Arsenal lo wa ni ipo to kangun si eleyi ko kẹyin lori tabili EPL. Arteta ta Pàù! Lukaku lagi mọ́ Arsenal lórí láti gbayì fún Chelsea Gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lo ti korin bọnu, ti wọn si n fi ẹgbẹ agbaọọlu arsenal ṣe ẹlẹya lẹyin ti wọmn ko wọn ni bulala meji si odo Bi o ti lẹ jẹ pe igba meji pere ni Arsenal ti gba bọọlu bi saa premiere liigi to bẹrẹ yìí, sibẹ wọn ko ti gba pọnti kankan, bakan naa ni wọn sọ oore- ọfẹ lati gba bọọlu sawọn nu ni ẹẹmẹrin. Awọn ọmọ ikọ agbabọọlu Chelsae ti fakọyọ ni ẹẹmeji ti wọn ti dije ni saayii, ti wọn si ti jẹ nigba marun, koda, Romelu Lukaku ti wọn ṣẹsẹ kowo le lori se gudugujdu meje yaya mẹfa ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ to ti waye yii. Lilọ bibọ Lukaku yii gan lo dabi orififọ fun ikọ agbaọọlu Arsenal James pẹlu naa ko gbẹyin bi oun ati Mason ṣe jọ n ran ara wọn lọwọ lati goolu keji Diẹ lo ku ki Lukaku tun jẹ goolu kẹta sùgbọn ṣe lo fi ori gba bọọlu na lu irin oju ile. O jọ bi ẹni pe Ben White to yẹ ko dile mu lọwọ ẹyin fun Arsenal ti ko si nibẹ nitori aarun Covid-19 to de mọọlẹ o jẹ nnkan to n yọ Arsenal lẹnu . Nnkan ti oju Arsenal ti ri laarin ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn ti gba ni saa yii ti fẹ buru ju ti saa liigi to kọja lọ. Igba kẹta ree, ti ikọ agbaọọlu Arsenal yoo fidirẹmi ninu idije meji ni tẹlẹntẹle ni saa liigi tuntun Ibeere ti ọpọ n bere ni pe, ṣe Arteta ko duro gba sabuke lọwọ Pep guardiola to ti kọsẹ ni? | https://www.bbc.com/yoruba/media-58300499 |
1entertainment
| Ekifest '19: Ohun t'ọ́kùnrin ń ṣe l'Ekiti, obìnrin lè ṣe é | Nibi ayẹyẹ ajọdun aṣa ọdun yii ni ipinlẹ Ekiti, oniruuru ohun tẹ o tilẹ mọ pe o wa laye yii lẹ o ri nibẹ. Adari ileeṣẹ Aṣa ni ipinlẹ Ekiti, Wale Ojo sọ fun BBC Yoruba pe awọn n ko awọn aṣa awọn jade lati ṣe afihan rẹ faraye ni. "A sọ ijó di owó, ohun t'ọ́kùnrin ń ṣe l'Ekiti, obìnrin lè ṣe é". Ọgbni Wale sọ pe Ekiti Festival ti mú ọlá àti oríire wọ ìlú Ekiti, "o n gbe ọgbọn inu ati imọ awọn ọdọ jade sita". O tẹsiwaju pe gbogbo ìlú tó wà ní Africa ló kù tí Ekiti máa fìwé pè lọ́dún 2020 lati wa wo ọgbọ, imọ ati oye ti Ọlọrun fi sọlẹ si ilu Ekiti. Lóòtọ́ lóòtọ́, kò sí àṣàdànù nínú àwọ́n afihan ohun agbaṣa ga to waye nibi EKiti Festival 2019. Marlian, òfégè ìgbéyàwó Buhari, Fatoyinbo àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá tó mi ìgboro tìtì ní 2019 Bukola Saraki fi 'Gbas Gbos' ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí 'ilẹ̀ bàbá rẹ̀' tí ìjọba Kwara gbà padà Oluwo àti Olorì àná, Chanel Chin tahùn síra Lórúkọ ìdílé Diya, a gbúdọ̀ ti ẹsẹ̀ òfin bọ ìkú tó mú ọkọ àti ọmọ méjì lọ - Agbẹjọ́rò Ṣé ẹ mọ̀ pé Ekiti ni ìlú tí Ògún Lákááyé wọlẹ̀ sí? Ilu Orunmila naa, Ekiti ni. Eṣu tó ma ń dá àbò bo àwọn èèyàn tirẹ̀, Eṣu Ẹlẹ́gbẹ̀rà to maa n gba awọn eeyan lọjọ ibi ba de, ilu Ekiti ni gbogbo wọn ti wa gẹg bi adari aṣa ipinlẹ naa ṣe sọ ọ. Iyawo gomina ipinlẹ Ekiti, Erelu Bisi Fayemi kadi eto ajdun naa pẹlu rọ̀ iwuri nipa Ekiti pe "Orin Ekiti dá yàtọ̀, ijó wọn, oke nla nla atawọn nkan to jẹ pe owo lawọn eeyan fi lọ n wo wọn nibomiran". | Ekifest '19: Ohun t'ọ́kùnrin ń ṣe l'Ekiti, obìnrin lè ṣe é Nibi ayẹyẹ ajọdun aṣa ọdun yii ni ipinlẹ Ekiti, oniruuru ohun tẹ o tilẹ mọ pe o wa laye yii lẹ o ri nibẹ. Adari ileeṣẹ Aṣa ni ipinlẹ Ekiti, Wale Ojo sọ fun BBC Yoruba pe awọn n ko awọn aṣa awọn jade lati ṣe afihan rẹ faraye ni. "A sọ ijó di owó, ohun t'ọ́kùnrin ń ṣe l'Ekiti, obìnrin lè ṣe é". Ọgbni Wale sọ pe Ekiti Festival ti mú ọlá àti oríire wọ ìlú Ekiti, "o n gbe ọgbọn inu ati imọ awọn ọdọ jade sita". O tẹsiwaju pe gbogbo ìlú tó wà ní Africa ló kù tí Ekiti máa fìwé pè lọ́dún 2020 lati wa wo ọgbọ, imọ ati oye ti Ọlọrun fi sọlẹ si ilu Ekiti. Lóòtọ́ lóòtọ́, kò sí àṣàdànù nínú àwọ́n afihan ohun agbaṣa ga to waye nibi EKiti Festival 2019. Marlian, òfégè ìgbéyàwó Buhari, Fatoyinbo àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá tó mi ìgboro tìtì ní 2019 Bukola Saraki fi 'Gbas Gbos' ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí 'ilẹ̀ bàbá rẹ̀' tí ìjọba Kwara gbà padà Oluwo àti Olorì àná, Chanel Chin tahùn síra Lórúkọ ìdílé Diya, a gbúdọ̀ ti ẹsẹ̀ òfin bọ ìkú tó mú ọkọ àti ọmọ méjì lọ - Agbẹjọ́rò Ṣé ẹ mọ̀ pé Ekiti ni ìlú tí Ògún Lákááyé wọlẹ̀ sí? Ilu Orunmila naa, Ekiti ni. Eṣu tó ma ń dá àbò bo àwọn èèyàn tirẹ̀, Eṣu Ẹlẹ́gbẹ̀rà to maa n gba awọn eeyan lọjọ ibi ba de, ilu Ekiti ni gbogbo wọn ti wa gẹg bi adari aṣa ipinlẹ naa ṣe sọ ọ. Iyawo gomina ipinlẹ Ekiti, Erelu Bisi Fayemi kadi eto ajdun naa pẹlu rọ̀ iwuri nipa Ekiti pe "Orin Ekiti dá yàtọ̀, ijó wọn, oke nla nla atawọn nkan to jẹ pe owo lawọn eeyan fi lọ n wo wọn nibomiran". | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-50944211 |
5sports
| World Cup 2022 - Bí ó ṣe ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ìdíjé Ife Agbaye | Ọgunjọ, Osu Kọkanla ni ife ẹyẹ agbaye, Qatar 2022 yoo bẹrẹ ni ọjọ kejidinlogun, oṣu kejila, ni ọdun 2022. Igba kejilelogun ti idije yii yoo ma waye niyii. Eleyii si jẹ igba akọkọ ti wọn yoo gba bọọlu naa ni orilẹede Arabu. BBC ṣe akojọpọ bi ifẹṣẹwọnṣẹ yoo ṣe lọ ati esi ifẹwọnsẹ ni idije Ife Ẹyẹ agbaye Qatar, 2022. | World Cup 2022 - Bí ó ṣe ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ìdíjé Ife Agbaye Ọgunjọ, Osu Kọkanla ni ife ẹyẹ agbaye, Qatar 2022 yoo bẹrẹ ni ọjọ kejidinlogun, oṣu kejila, ni ọdun 2022. Igba kejilelogun ti idije yii yoo ma waye niyii. Eleyii si jẹ igba akọkọ ti wọn yoo gba bọọlu naa ni orilẹede Arabu. BBC ṣe akojọpọ bi ifẹṣẹwọnṣẹ yoo ṣe lọ ati esi ifẹwọnsẹ ni idije Ife Ẹyẹ agbaye Qatar, 2022. | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-63643388 |
5sports
| Community Shield: Man City fọ́ Liverpool lẹ́nu bẹ̀rẹ̀ sáà bọ́ọ̀lù tuntun ní Wembley | Ajura wa lọ tijankandi kọ o! Manchester City ṣina iya fun Liverpool lati gba ife ẹyẹ community Shield ni papa iṣere Wembley. Man City naa lo gba ife ẹyẹ Premier League Liverpool lọwọ ni saa bọọlu to lọ. Raheem Sterling lo kọkọ gbayo wọ le fu Man City ṣugbọn Joel Matip sayo naa pada, lo ba di ọmi alayo kọọkan. Wo mi ki n gba siọ ti wọn n pe ni pẹnariti ni wọn yanju rẹ. Manchester City lo papa jawe olubori lẹyin ti wọn gba pẹnariti wọ le ti Liverpool si le da mẹrin pada. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester City àti Liverpool ṣíde sáà bọ́ọ̀lù tuntun Saa bọọlu tuntun bẹrẹ lọjọ Aiku, ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ, Manchester City ti wọn gba ife ẹyẹ Premier League ni saa to lọ yoo ṣide saa tuntun pẹlu Liverpool tawọn gba ife ẹyẹ UEFA Champions League. Man City tun gba ife ẹyẹ FA, bẹẹ ni wọn ti Carabao Cup, awọn kan tiẹ sọ pe ife mẹrin ni wọn gba lẹyin ti wọn ṣina iya fun Chelsea ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield ti saa bọọlu to lọ. Man City gba ife ẹyẹ Premier League pẹlu ami ayo mejidinlọgọrun un nigba ti Liverpool tẹle wọn pẹlu ami ayo mẹtadinlọgọrun. Asiko tun ti to lati bẹrẹ iwọ o ju mi, emi o ju ọ lẹẹkan si, aago mẹta ọsan ọjọ Aiku ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo bẹrẹ ni papa iṣere Wembley niluu London. Aṣole fun Manchester City Ederson ati agbabọọlu aaringbungbun Fernandinho ko ni le kopa ninu ere bọọlu naa, nitori o pẹ diẹ ki wọn to pada de lẹyin ti wọn ṣoju Brazil ninu idije Copa America, Claudio Bravo Bravo ni yoo dile mu fun Man City ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun. Bakan naa, Sadio Mane ko ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield nitori oun naa ṣẹṣẹ de lati idije AFCON 2019 nibi ti orilẹede rẹ, Senegal fidi rẹmi ninu aṣekagba idije naa. Igba akọkọ re e ti Liverpool yoo kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield lati ọdun 2006 nigba ti na Chelsea pẹlu ami ayo meji sẹyọkan. Eyi ni igba kejila ti Man City yoo kopa ninu Community Shield, wọn si ti gba ife naa lẹẹmarun un . | Community Shield: Man City fọ́ Liverpool lẹ́nu bẹ̀rẹ̀ sáà bọ́ọ̀lù tuntun ní Wembley Ajura wa lọ tijankandi kọ o! Manchester City ṣina iya fun Liverpool lati gba ife ẹyẹ community Shield ni papa iṣere Wembley. Man City naa lo gba ife ẹyẹ Premier League Liverpool lọwọ ni saa bọọlu to lọ. Raheem Sterling lo kọkọ gbayo wọ le fu Man City ṣugbọn Joel Matip sayo naa pada, lo ba di ọmi alayo kọọkan. Wo mi ki n gba siọ ti wọn n pe ni pẹnariti ni wọn yanju rẹ. Manchester City lo papa jawe olubori lẹyin ti wọn gba pẹnariti wọ le ti Liverpool si le da mẹrin pada. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester City àti Liverpool ṣíde sáà bọ́ọ̀lù tuntun Saa bọọlu tuntun bẹrẹ lọjọ Aiku, ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ, Manchester City ti wọn gba ife ẹyẹ Premier League ni saa to lọ yoo ṣide saa tuntun pẹlu Liverpool tawọn gba ife ẹyẹ UEFA Champions League. Man City tun gba ife ẹyẹ FA, bẹẹ ni wọn ti Carabao Cup, awọn kan tiẹ sọ pe ife mẹrin ni wọn gba lẹyin ti wọn ṣina iya fun Chelsea ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield ti saa bọọlu to lọ. Man City gba ife ẹyẹ Premier League pẹlu ami ayo mejidinlọgọrun un nigba ti Liverpool tẹle wọn pẹlu ami ayo mẹtadinlọgọrun. Asiko tun ti to lati bẹrẹ iwọ o ju mi, emi o ju ọ lẹẹkan si, aago mẹta ọsan ọjọ Aiku ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo bẹrẹ ni papa iṣere Wembley niluu London. Aṣole fun Manchester City Ederson ati agbabọọlu aaringbungbun Fernandinho ko ni le kopa ninu ere bọọlu naa, nitori o pẹ diẹ ki wọn to pada de lẹyin ti wọn ṣoju Brazil ninu idije Copa America, Claudio Bravo Bravo ni yoo dile mu fun Man City ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun. Bakan naa, Sadio Mane ko ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield nitori oun naa ṣẹṣẹ de lati idije AFCON 2019 nibi ti orilẹede rẹ, Senegal fidi rẹmi ninu aṣekagba idije naa. Igba akọkọ re e ti Liverpool yoo kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield lati ọdun 2006 nigba ti na Chelsea pẹlu ami ayo meji sẹyọkan. Eyi ni igba kejila ti Man City yoo kopa ninu Community Shield, wọn si ti gba ife naa lẹẹmarun un . | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-49227723 |
4religion
| Wòlíì Kasali sọ̀rọ̀ nípa awuyewuye pé ó lé ìyàwó rẹ̀ jáde nílé | Bi wọn ba ni ki pe eeyan to padanu oju ita wa ṣugbọn ti oju inu rẹ n rina daada wa,Woli Kasali nilu Ibadan jẹ irufẹ eeyan bẹ. Ilumọka ajihinrere naa jẹ afọju lootọ sugbọn lọdọ awọn to jẹ ọmọ ijọ rẹ, kii ṣe afọju lasan. Awọn to mọ ni a ma riran si awọn eeyan ti a si ma woye nipa iṣẹlẹ orisirisi lawujọ. Iko BBC Yoruba tọ Woli Kasalai lọ lati beere ọrọ nipa iṣe rẹ ati awọn nnkan miran to fi mọ iroyin to n ja rainrain nipa oun ati iyawo rẹ ti wọn ni o le sita. Woli Kasali ṣe ọpọlọpọ alaye to si ni kii ṣe wi pe oun mọmọ le iyawo oun jade bii kii ṣe wi pe oun fun ararẹ lo kẹru kuro nile. ''Mo kuku fẹran Bunmi daa,tori wi pe ọrọ to gun,ọrọ igbesi aaye mi lẹ n beere yen'' O salaye wi pe ko si ootọ ninu ọrọ wi pe oun da Bunmi sita pẹlu ọmọ maarun nitori orekelẹwa Dolapo Awosika. ''Dolapo Awosika ko wa gba ọkọ kankan lọwọ Bunmi.Oun ti o ba wa yatọ.Dolapo ko le ọlọmọ maruun sita,ko ba nile'' Ṣé àwọn ọmọ rẹ lè sọ Yorùbá tó àwọn ọmọ Amẹrika yìí? | Wòlíì Kasali sọ̀rọ̀ nípa awuyewuye pé ó lé ìyàwó rẹ̀ jáde nílé Bi wọn ba ni ki pe eeyan to padanu oju ita wa ṣugbọn ti oju inu rẹ n rina daada wa,Woli Kasali nilu Ibadan jẹ irufẹ eeyan bẹ. Ilumọka ajihinrere naa jẹ afọju lootọ sugbọn lọdọ awọn to jẹ ọmọ ijọ rẹ, kii ṣe afọju lasan. Awọn to mọ ni a ma riran si awọn eeyan ti a si ma woye nipa iṣẹlẹ orisirisi lawujọ. Iko BBC Yoruba tọ Woli Kasalai lọ lati beere ọrọ nipa iṣe rẹ ati awọn nnkan miran to fi mọ iroyin to n ja rainrain nipa oun ati iyawo rẹ ti wọn ni o le sita. Woli Kasali ṣe ọpọlọpọ alaye to si ni kii ṣe wi pe oun mọmọ le iyawo oun jade bii kii ṣe wi pe oun fun ararẹ lo kẹru kuro nile. ''Mo kuku fẹran Bunmi daa,tori wi pe ọrọ to gun,ọrọ igbesi aaye mi lẹ n beere yen'' O salaye wi pe ko si ootọ ninu ọrọ wi pe oun da Bunmi sita pẹlu ọmọ maarun nitori orekelẹwa Dolapo Awosika. ''Dolapo Awosika ko wa gba ọkọ kankan lọwọ Bunmi.Oun ti o ba wa yatọ.Dolapo ko le ọlọmọ maruun sita,ko ba nile'' Ṣé àwọn ọmọ rẹ lè sọ Yorùbá tó àwọn ọmọ Amẹrika yìí? | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-46691476 |
2health
| Coronavirus: Ọmọ ilẹ̀ Italy tó kó Coronavirus wọ Naijiria kò ní àrùn náà mọ́ | Ayẹwo ti fi han pe ọmọ orilẹde Italy to ko arun Coronavirus wọn Naijiria ko ni arun naa mọ. Ṣaaju ni ọkunrin ọhun to wa si Naijiria lati ilu Milan lọjọ kẹrinlelogun, Oṣu Keji ọdun yii ti n gba itọju nile iwosan ijọba to wa ni yaba, nilu Eko. Kọmiṣọna eto ilera ipinlẹ Eko, Akin Abayomi sọ fun awọn akọroyin nibi ifọrọwerọ kan pe ẹni ọdun mẹrinlelogoji naa ko ni arun ọhun lara mọ. Abayomi tẹsiwaju pe wọn yoo ṣe ayẹwo mii fun ọkunrin naa, ti esi rẹ ba wa bakan naa, wọn yoo da silẹ ko ma lọ ile rẹ layọ ati alafia. O ni "Ọkunrin naa ko ni arun Coronavirus lara mọ, ṣugbọn idi ti a ṣi fi da duro ni pe a fẹ ṣe ayẹwo miran fun ki a to fi silẹ ko maa lọ ile rẹ." Ọmọ ilẹ Italy naa wọ sile itura kan to sunmọ papakọ ofurufu ilu Eko ni kete to gunlẹ si Naijiria, ko to lọ si ipinlẹ Ogun fun iṣẹ aje. Ọjọ kẹta to de si Naijiria ti lo ṣaisan rampẹ, ti ayẹwo si fi han pe arun Coronavirus lo n ba finra. Ẹẹdẹgbeje (1300) awọn eeyan lawọn ileeṣẹ eto ilera n wa bayii lori itankalẹ arun coronavirus ọhun. Kọmiṣọna feto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi lo ṣalaye eyi lẹyin to kede eeyan mẹrin miran pẹlu arun Coronavirus bayii. Eyii ti mu ki apapọ awọn eeyan to ni arun naa ni Naijiria pe mejila bayii. Ọjọgbọn Abayọmi ni ayẹwo mọkandinlogun ni wọn ṣe lori awọn ti wọn funrasi pe wọn ni aarun naa atawọn eeyan to ni nnkan pọ pẹlu awọn awọn marun ti wọn kede pe wọn ni arun naa lọjọru. Mẹrin ninu ayẹwo ọhun lo ja si tootọ. O ni akọkọ ninu wọn ni ọmọbinrin ọmọ orilẹede Naijiria kan to wọ orilẹede Naijiria lati orilẹede France pẹlu baluu ilẹ Turkey kan lọjọ kẹrinla oṣu kẹta ọdun 2020. O fi kun pe ẹni keji ni ọmọkunrin kan ti ọjọ ori rẹ ti le ni aadọta ti ko rinrinajo lọ si ibikibi. Ẹnikẹta ni arakunrin miran to wọ orilẹede Naijiria ni ọjọ kẹtala oṣu kẹta lati ilu Frankfurt lorilẹede Germany. O ni ẹẹdẹgbeje awọn eeyan lawọn ileeṣẹ eto ilera n wa bayii lori itankalẹ arun coronavirus ọhun. | Coronavirus: Ọmọ ilẹ̀ Italy tó kó Coronavirus wọ Naijiria kò ní àrùn náà mọ́ Ayẹwo ti fi han pe ọmọ orilẹde Italy to ko arun Coronavirus wọn Naijiria ko ni arun naa mọ. Ṣaaju ni ọkunrin ọhun to wa si Naijiria lati ilu Milan lọjọ kẹrinlelogun, Oṣu Keji ọdun yii ti n gba itọju nile iwosan ijọba to wa ni yaba, nilu Eko. Kọmiṣọna eto ilera ipinlẹ Eko, Akin Abayomi sọ fun awọn akọroyin nibi ifọrọwerọ kan pe ẹni ọdun mẹrinlelogoji naa ko ni arun ọhun lara mọ. Abayomi tẹsiwaju pe wọn yoo ṣe ayẹwo mii fun ọkunrin naa, ti esi rẹ ba wa bakan naa, wọn yoo da silẹ ko ma lọ ile rẹ layọ ati alafia. O ni "Ọkunrin naa ko ni arun Coronavirus lara mọ, ṣugbọn idi ti a ṣi fi da duro ni pe a fẹ ṣe ayẹwo miran fun ki a to fi silẹ ko maa lọ ile rẹ." Ọmọ ilẹ Italy naa wọ sile itura kan to sunmọ papakọ ofurufu ilu Eko ni kete to gunlẹ si Naijiria, ko to lọ si ipinlẹ Ogun fun iṣẹ aje. Ọjọ kẹta to de si Naijiria ti lo ṣaisan rampẹ, ti ayẹwo si fi han pe arun Coronavirus lo n ba finra. Ẹẹdẹgbeje (1300) awọn eeyan lawọn ileeṣẹ eto ilera n wa bayii lori itankalẹ arun coronavirus ọhun. Kọmiṣọna feto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi lo ṣalaye eyi lẹyin to kede eeyan mẹrin miran pẹlu arun Coronavirus bayii. Eyii ti mu ki apapọ awọn eeyan to ni arun naa ni Naijiria pe mejila bayii. Ọjọgbọn Abayọmi ni ayẹwo mọkandinlogun ni wọn ṣe lori awọn ti wọn funrasi pe wọn ni aarun naa atawọn eeyan to ni nnkan pọ pẹlu awọn awọn marun ti wọn kede pe wọn ni arun naa lọjọru. Mẹrin ninu ayẹwo ọhun lo ja si tootọ. O ni akọkọ ninu wọn ni ọmọbinrin ọmọ orilẹede Naijiria kan to wọ orilẹede Naijiria lati orilẹede France pẹlu baluu ilẹ Turkey kan lọjọ kẹrinla oṣu kẹta ọdun 2020. O fi kun pe ẹni keji ni ọmọkunrin kan ti ọjọ ori rẹ ti le ni aadọta ti ko rinrinajo lọ si ibikibi. Ẹnikẹta ni arakunrin miran to wọ orilẹede Naijiria ni ọjọ kẹtala oṣu kẹta lati ilu Frankfurt lorilẹede Germany. O ni ẹẹdẹgbeje awọn eeyan lawọn ileeṣẹ eto ilera n wa bayii lori itankalẹ arun coronavirus ọhun. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51957241 |
3politics
| ALGON Oyo: Àwọn alága káńṣù APC fẹ́ kí ẹjọ́ ọ̀hún tẹ̀síwájú | Ijọba ipinlẹ Oyo ti gbe igbesẹ lati pari rogbodiyan to n waye ni itubi inubi, laarin rẹ ati awọn alaga Kansu, to ni ki wọn lọ rọkun nile. Agbẹjọro fun ijọba, Akin Onigbinde lo sọ ọrọ naa niwaju adajọ Mashud Abass, nibi igbẹjọ to n lọ lọwọ lori họwuhọwu to bẹ lẹyin idaduro awọn alaga ọhun. O ni ijọba ti pinnu pe ki wọn lọ yanju ọrọ naa laarin ara wọn, ki alaafia lee jọba nipinlẹ Oyo. Onigbinde sọ fun adajọ naa pe, wọn yoo pada si ile ẹjọ ti wọn ba kuna lati pari aawọ laarin ara wọn. Ṣugbọn awọn agbejọro fun awọn alaga ijọba ibilẹ ti wọn da duro, Niyi Akintola ati Kunle Sobolaju sọ pe, igbesẹ yii ko tẹ awọn lọrun. Wọn ni ile ẹjọ gbọdọ da ẹjọ naa nu, ki wọn to lee pari aawọ naa ni itubi inubi. Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeji, adajọ Mashud Abass ki awọn agbẹjọro ku iṣẹ takuntakun, to si ni ki wọn lọ yanju ẹjọ naa laarin ara wọn, ki wọn si tun ri daju pe alafia jọba nipinlẹ Oyo. Ile ẹjọ ọhun wa sun ẹjọ naa si ọjọ kejila Oṣu Keji ọdun 2020, lati mọ ibi ti ọrọ de duro, bi bẹẹkọ, oun yoo tẹsiwaju lati gbọ ẹjọ naa. Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Karun un ọdun 2019 ni gomina Seyi Makinde yọ awọn alaga ijọba ibilẹ naa bi ẹni yọ jiga, to si yan awọn alaga fidihẹ. Sugbọn awọn alaga naa fẹ fi tipatipa pada ṣẹnu iṣẹ eyi to da rogbodiyan silẹ. | ALGON Oyo: Àwọn alága káńṣù APC fẹ́ kí ẹjọ́ ọ̀hún tẹ̀síwájú Ijọba ipinlẹ Oyo ti gbe igbesẹ lati pari rogbodiyan to n waye ni itubi inubi, laarin rẹ ati awọn alaga Kansu, to ni ki wọn lọ rọkun nile. Agbẹjọro fun ijọba, Akin Onigbinde lo sọ ọrọ naa niwaju adajọ Mashud Abass, nibi igbẹjọ to n lọ lọwọ lori họwuhọwu to bẹ lẹyin idaduro awọn alaga ọhun. O ni ijọba ti pinnu pe ki wọn lọ yanju ọrọ naa laarin ara wọn, ki alaafia lee jọba nipinlẹ Oyo. Onigbinde sọ fun adajọ naa pe, wọn yoo pada si ile ẹjọ ti wọn ba kuna lati pari aawọ laarin ara wọn. Ṣugbọn awọn agbejọro fun awọn alaga ijọba ibilẹ ti wọn da duro, Niyi Akintola ati Kunle Sobolaju sọ pe, igbesẹ yii ko tẹ awọn lọrun. Wọn ni ile ẹjọ gbọdọ da ẹjọ naa nu, ki wọn to lee pari aawọ naa ni itubi inubi. Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeji, adajọ Mashud Abass ki awọn agbẹjọro ku iṣẹ takuntakun, to si ni ki wọn lọ yanju ẹjọ naa laarin ara wọn, ki wọn si tun ri daju pe alafia jọba nipinlẹ Oyo. Ile ẹjọ ọhun wa sun ẹjọ naa si ọjọ kejila Oṣu Keji ọdun 2020, lati mọ ibi ti ọrọ de duro, bi bẹẹkọ, oun yoo tẹsiwaju lati gbọ ẹjọ naa. Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Karun un ọdun 2019 ni gomina Seyi Makinde yọ awọn alaga ijọba ibilẹ naa bi ẹni yọ jiga, to si yan awọn alaga fidihẹ. Sugbọn awọn alaga naa fẹ fi tipatipa pada ṣẹnu iṣẹ eyi to da rogbodiyan silẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51396115 |
1entertainment
| Yollywood: Gbajúmọ̀ òṣèré, Ijebu ní Ọgbọ́n lòun fi ń yẹra fún gbọ́yísọ̀yí lágbo àwọn òṣèré | Gbajumọ apanilẹrin lagbo sinima ede Yoruba, Tayọ Amokade ti ọpọ eeyan mọ si Ijebu ti ṣalaye fun araye pe ati dide goke ko rọgbọ fun oun nitoripe awọn iṣẹ ti ọpọ ko fi oju rena ni oun ti ṣe ki itanṣan ọla to tan si oun. Ijẹbu ṣalaye ninu ifọrọwanilẹwo kan pe iṣẹ ẹrọ amunawa, jẹnẹretọ titunṣe loun n ṣe ki oun to di ilumọọka oṣere. Bakan naa lo ṣalaye nipa oniruuru ijakulẹ ti oun dojukọ ki aye to mọ oun. "Iṣẹ ẹrọ amunawa, jẹnẹretọ titunṣe ni mo kọkọ fi bẹrẹ. Mo jẹ eeyan ti kii fi iṣẹ jafara rara, gbogbo anfani ti mo ba si ri ni mo maa n mu lọkunkundun." Bakan naa lo tun sọrọ lori awọn awuyewuye to maa n waye lagbo awọn oṣere to si ni, oun n gbiyanju ni igba gbogbo lati yẹra fun ẹrẹ awuyewuye to n waye lẹka naa. O ni bi o ti wulẹ wu ki oṣere sare to lati yẹera fun awọn gbọyisọyi lagbo amuludun, awọn iṣẹlẹ ori ayelujara ti jẹ ko ṣoro pupọ. | Yollywood: Gbajúmọ̀ òṣèré, Ijebu ní Ọgbọ́n lòun fi ń yẹra fún gbọ́yísọ̀yí lágbo àwọn òṣèré Gbajumọ apanilẹrin lagbo sinima ede Yoruba, Tayọ Amokade ti ọpọ eeyan mọ si Ijebu ti ṣalaye fun araye pe ati dide goke ko rọgbọ fun oun nitoripe awọn iṣẹ ti ọpọ ko fi oju rena ni oun ti ṣe ki itanṣan ọla to tan si oun. Ijẹbu ṣalaye ninu ifọrọwanilẹwo kan pe iṣẹ ẹrọ amunawa, jẹnẹretọ titunṣe loun n ṣe ki oun to di ilumọọka oṣere. Bakan naa lo ṣalaye nipa oniruuru ijakulẹ ti oun dojukọ ki aye to mọ oun. "Iṣẹ ẹrọ amunawa, jẹnẹretọ titunṣe ni mo kọkọ fi bẹrẹ. Mo jẹ eeyan ti kii fi iṣẹ jafara rara, gbogbo anfani ti mo ba si ri ni mo maa n mu lọkunkundun." Bakan naa lo tun sọrọ lori awọn awuyewuye to maa n waye lagbo awọn oṣere to si ni, oun n gbiyanju ni igba gbogbo lati yẹra fun ẹrẹ awuyewuye to n waye lẹka naa. O ni bi o ti wulẹ wu ki oṣere sare to lati yẹera fun awọn gbọyisọyi lagbo amuludun, awọn iṣẹlẹ ori ayelujara ti jẹ ko ṣoro pupọ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-59295424 |
1entertainment
| Fathia Balogun: Ilúmọọka oṣere tiata, Fathia Balogun ṣetan lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lọna ara. | Ẹni ọdun ba ba laye, o yẹ ko se ọpẹ paapaa ọjọ ibi nitori eyi la maa fi n dupẹ fun Oluwa pe o da mi wa si lari ri ọdun tuntun. Boya eyi lo mu ki gbajugbaja osere tiata, Faithia Balogun, to fi seto ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ fun ọdun ta wa yii ni ọna ara. Fathia, to pe akori ayẹyẹ ọjọ ibi naa ni ‘Faithia Unusual 2022’ ni ayẹy ọjọ ibi naa yoo waye lọjọ ketadinlogbọn oṣu keji ọdun 2022. Bakan naa lo ti fi ekunrẹrẹ bi eto naa yoo ṣe lọ sori oju opo Instagram Bimbo Thomas, ọkan lara awọn akẹẹgbẹ rẹ lobinrin lagbo ere tiata. Ikede bi owo asọ ẹbi naa yoo si se lọ ni Bimbo Thomas kede eyi to ni yoo jẹ ki awọn eeyan rere to nifẹ mọ nipa ayẹyẹ naa le mọ bo se yẹ Ninu ohun ti o wa loju opo Bimbo Thomas, oriṣiiriṣii aṣọ ẹbí lo wa fawọn alejo ti yoo wa sibi ayẹyẹ ọjọ ibi naa. Isọri aṣọ ẹbí Platinum fawọn obinrin lo wọn julọ, ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (₦150k) ni aṣọ naa pẹlu gele. Isọri platinum fawọn ọkunrin, ẹgbẹrun lọna ọgọfa (₦120,000) ni aṣọ naa tii ṣe agbada ati fila. Ni isọri gold, ẹgbẹrun lọna ọgọta naira (₦60,000) ni aṣọ awọn obinrin pẹlu gele. Bakan naa ni isọri gold, ẹgbẹrun lọna ọgọta naira ni aṣọ awọn ọkunrin bakan naa. O wa fi apo asuwọn owo ile ifowopamọ sibẹ fun awọn eeyan to nifẹ lati ra asọ ẹbi naa pe ki wọn san owo si. Bakan naa lo sọ fun wọn pe ki wọn fi risiti, eyiun ẹri pe wọn ti san owo naa sọwọ si oun gẹgẹ bi idaniloju pe lootọ ni wọn ti sanwo asọ ẹbi naa. Ko tan sibẹ o, Ọlọjọ ibi tun kọ sibi ikede naa gadagba pe funra awọn eeyan to ba ra asọ ọjọ ibi oun ni wọn yoo san owo ọkọ fun ẹni ti yoo gbe asọ naa wa fun wọn nile. Koda gan, lọjọ ibi funra r ti gbe ikede nipa ọjọ ibi naa soju opo Instagram rẹ. Nigba ti awọn eeyan kan n foju sọna fun ọjọ ibi ọhún, niṣe l'awọn mii n beere wi pe nibo l'awọn ilumọọka oṣere tiata ti n rowo ti wọn n na lati fi ra asọ ẹbi gbogbo igba. Koda kan ninu wọn ni plu bi wọn se n ra asọ ẹbi lọsọọsẹ yii, se wọn yoo ni ajẹsẹku bi? Bi ọjọ ibi ọhun ti n kan ilẹkun gbọngbọn, awọn akẹgbẹ rẹ ti bẹrẹ si ni sọ nipa ayẹyẹ ọjọ ibi naa ti yoo waye nile itura kan niluu Eko. Ọdun 1971 ni wọn bi Faithia Balogun niluu Eko bo tilẹ jẹ pe ọmọbibi ipinlẹ Delta l'awọn obi rẹ. Ile ẹkọ alakọbẹrẹ Maryland ni Faithia lọ niluu Eko. O tun tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ nile ẹkọ girama Maryland Comprehensive Secondary School. Faithia lọ si ile ẹkọ gbogbonṣe Kwara Poly ki o to tẹsiwaju ni fasiti Olabisi Onabanjo nibi to ti gboye ninu ẹkọ ere ori itage. Faithia jẹ oṣere, olootu ati adari ere. O si ti gba oriṣiiriṣii ami ẹyẹ lẹnu iṣẹ ere ori itage ati igba to ti bẹrẹ iṣẹ ere ori itage. Faithia ṣe igbeyawo pẹlu akẹgbẹ rẹ, Saheed Balogun. Eledumare si fi ọmọbinrin kan ati ọmọkùnrin kan t'awọn lọrẹ. | Fathia Balogun: Ilúmọọka oṣere tiata, Fathia Balogun ṣetan lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lọna ara. Ẹni ọdun ba ba laye, o yẹ ko se ọpẹ paapaa ọjọ ibi nitori eyi la maa fi n dupẹ fun Oluwa pe o da mi wa si lari ri ọdun tuntun. Boya eyi lo mu ki gbajugbaja osere tiata, Faithia Balogun, to fi seto ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ fun ọdun ta wa yii ni ọna ara. Fathia, to pe akori ayẹyẹ ọjọ ibi naa ni ‘Faithia Unusual 2022’ ni ayẹy ọjọ ibi naa yoo waye lọjọ ketadinlogbọn oṣu keji ọdun 2022. Bakan naa lo ti fi ekunrẹrẹ bi eto naa yoo ṣe lọ sori oju opo Instagram Bimbo Thomas, ọkan lara awọn akẹẹgbẹ rẹ lobinrin lagbo ere tiata. Ikede bi owo asọ ẹbi naa yoo si se lọ ni Bimbo Thomas kede eyi to ni yoo jẹ ki awọn eeyan rere to nifẹ mọ nipa ayẹyẹ naa le mọ bo se yẹ Ninu ohun ti o wa loju opo Bimbo Thomas, oriṣiiriṣii aṣọ ẹbí lo wa fawọn alejo ti yoo wa sibi ayẹyẹ ọjọ ibi naa. Isọri aṣọ ẹbí Platinum fawọn obinrin lo wọn julọ, ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (₦150k) ni aṣọ naa pẹlu gele. Isọri platinum fawọn ọkunrin, ẹgbẹrun lọna ọgọfa (₦120,000) ni aṣọ naa tii ṣe agbada ati fila. Ni isọri gold, ẹgbẹrun lọna ọgọta naira (₦60,000) ni aṣọ awọn obinrin pẹlu gele. Bakan naa ni isọri gold, ẹgbẹrun lọna ọgọta naira ni aṣọ awọn ọkunrin bakan naa. O wa fi apo asuwọn owo ile ifowopamọ sibẹ fun awọn eeyan to nifẹ lati ra asọ ẹbi naa pe ki wọn san owo si. Bakan naa lo sọ fun wọn pe ki wọn fi risiti, eyiun ẹri pe wọn ti san owo naa sọwọ si oun gẹgẹ bi idaniloju pe lootọ ni wọn ti sanwo asọ ẹbi naa. Ko tan sibẹ o, Ọlọjọ ibi tun kọ sibi ikede naa gadagba pe funra awọn eeyan to ba ra asọ ọjọ ibi oun ni wọn yoo san owo ọkọ fun ẹni ti yoo gbe asọ naa wa fun wọn nile. Koda gan, lọjọ ibi funra r ti gbe ikede nipa ọjọ ibi naa soju opo Instagram rẹ. Nigba ti awọn eeyan kan n foju sọna fun ọjọ ibi ọhún, niṣe l'awọn mii n beere wi pe nibo l'awọn ilumọọka oṣere tiata ti n rowo ti wọn n na lati fi ra asọ ẹbi gbogbo igba. Koda kan ninu wọn ni plu bi wọn se n ra asọ ẹbi lọsọọsẹ yii, se wọn yoo ni ajẹsẹku bi? Bi ọjọ ibi ọhun ti n kan ilẹkun gbọngbọn, awọn akẹgbẹ rẹ ti bẹrẹ si ni sọ nipa ayẹyẹ ọjọ ibi naa ti yoo waye nile itura kan niluu Eko. Ọdun 1971 ni wọn bi Faithia Balogun niluu Eko bo tilẹ jẹ pe ọmọbibi ipinlẹ Delta l'awọn obi rẹ. Ile ẹkọ alakọbẹrẹ Maryland ni Faithia lọ niluu Eko. O tun tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ nile ẹkọ girama Maryland Comprehensive Secondary School. Faithia lọ si ile ẹkọ gbogbonṣe Kwara Poly ki o to tẹsiwaju ni fasiti Olabisi Onabanjo nibi to ti gboye ninu ẹkọ ere ori itage. Faithia jẹ oṣere, olootu ati adari ere. O si ti gba oriṣiiriṣii ami ẹyẹ lẹnu iṣẹ ere ori itage ati igba to ti bẹrẹ iṣẹ ere ori itage. Faithia ṣe igbeyawo pẹlu akẹgbẹ rẹ, Saheed Balogun. Eledumare si fi ọmọbinrin kan ati ọmọkùnrin kan t'awọn lọrẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60172811 |
2health
| Coronavirus treatments: Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá pàṣẹ pé kò gbọdọ̀ sí ìdádúró fún àwọn tí iṣẹ́ wọn ṣe kókó lásíkò ìséde | Ẹgbẹ awọn dokita onimọ iṣegun oyinbo ni Naijiria ti fagile iyanṣẹlodi ti wọn bẹrẹ, nitori bi awọn ọlọpaa ṣe fiyajẹ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn kan lasiko isede coronavirus. Lara oun ti awọn dokita naa tọka si nipe ileeṣẹ ọlọpaa n da awọn ọmọ ẹgbẹ wọn duro, eyi ti ko yọ awọn ọkọ to n gbe alaisan silẹ. Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi sita, wọn ni ki awọn dokita o pada si ẹnu'ṣẹ wọn laago mẹfa irọlẹ oni. Iyanṣẹlodi naa ko pe wakati mejila ti wọn fi kede pe awọn ti fagile. Ọjọru ni wọn bẹrẹ iyanṣẹlodi naa, ti wọn si s pe yoo wa titi di igba ti ijọba yoo fopin si ifiyajẹni ti awọn ọlọpaa n ṣe si awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lasiko ofin Konile-o-gbele. Ninu atẹjade ti ẹgbẹ ọhun fi sita ni wọn ti fikun pe awọn ọlọpaa tilẹ n ti wọn mọle ni aini idi. Ṣugbọn ṣa, Ọga Agba Ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Muhammed Adamu paapa ti fi aṣẹ tuntun sita nipa ofin konile o-gbele kaakiri orilẹede Naijiria. Ko din ni aadọta awọn dokita , oniroyin atawọn oṣiṣẹ ẹka to ṣe koko miran lasiko ajakalẹ arun coronavirus yii ni awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti fi panpaẹ ofin mu bayii lọjọ Iṣẹgun ni ibamu pẹlu aṣẹ kan ti ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria pa. Ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹrin ni aarẹ Muhammadu Buhari paṣẹ konile o gbele eleyii to de igbokegbodo ọkọ laarin agogo mẹjọ alẹ si agogo mẹfa owurọ gẹgẹ bi ara ọna lati dena itankalẹ ajakalẹ orun COVID-19. Amọṣa aarẹ ko ṣai ṣe gafara fun awọn oṣiṣẹ ti iṣẹ wọn jẹ koṣemaani lasiko naa bii awọn oṣiṣẹ eto ilera, akọroyin ati bẹẹbẹl lọ. Ni ọjọ Iṣẹgun ni ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria ṣe ipade ori ayelujara pẹlu awọn lọgalọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa lorilẹ€de Naijiria nibi to ti paṣẹ fun wọn lati tubọ rii pe aṣẹ konile o gbele naa fẹsẹmulẹ sii ti wọn si ni o paṣẹ pe ki wọn maa fi panpẹ ofin mu ẹnikẹni ti irinkerindo rẹ ba ti kọja agogo mẹjọ alẹ. Lagbegbe Alausa ni ilu Eko, gbogbo awọn dokita ati akọroyin to n bọ lati ibi iṣẹ ni awsn ọlọpaa ko da satimọle ti wọn si gbẹsẹle ọkọ wọn. Iroyin taa gbọ ni pe awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ti aarẹ gbe kalẹ lori kikoju arun coronavirus, PTF lo wa kan si ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria ki o to paṣẹ ki wọn tu wọn silẹ lẹyin ti wọn ti lo bii wakati meji lagọ ọlọpaa. Ijọba ipinlẹ Eko ti n gbeero lati fi opin si isede coronavirus patapata, ṣugbọn diẹdiẹ ni yoo bẹrẹ. Gomina Babajide Sanwo-Olu lo kede awọn ilana tuntun yii, pẹlu boṣe jẹ pe ipinlẹ Eko ni aarun coronavirus pọ si julọ ni Naijiria. Ọsẹ keji ti ijọba dẹ isede lo n pari lọ bayii, ṣugbọn gomina sọ pe ọsẹ mẹfa ni yoo gba. 1. Register-to-Open - Eyi tumọ si pe ijọba yoo kọkọ ṣe ayẹwo ile ijọsin, ileeṣẹ, tabi ile itaja to ba fẹ ẹ bẹrẹ iṣẹ pada. 2. Lẹyin ayẹwo naa, ileeṣẹ, ile ijọsin, tabi ile itaja bẹ ẹ yoo gba iwe ẹri pe o pa ilana ati ofin ti ijọba gbe kalẹ lati fi opin si Covid-19. 3. Ijọba ko ti i sọ ọjọ ti awọn eeyan wọn yii yoo pada bẹrẹ iṣẹ wọn, lẹyin ayẹwo naa, ṣugbọn o sọ pe ki awọn to ni ileeṣẹ naa mura silẹ lati tẹle ilana tuntun naa, nitori pe coronavirus ti mu ayipada ba ayika wa. 4. Awọn ti ilana tuntun naa kan ni ṣọọṣi, mọṣalaaṣi, gbọngan ayẹyẹ, ile itaja igbalode nla, gbọngan sinima, ati awọn ibi igbafẹ. 5. Awọn nkan ti ijọba yoo yẹwo kii wọn o to o fun wọn ni iwe ẹri ni, ilana ijina sira ẹni ti wọn ti gbe kalẹ, ati fun imọtoto. Awọn nkan wọnyii ni yoo si sọ boya awọn ṣọọṣi ati mọṣalaaṣi naa yoo ṣi pada. 6. Ijọba yoo paṣẹ fun awọn banki, ati ọja lati maa da awọn onibara to jẹ agbalagba lohun laarin aago mẹsan aarọ si mẹwa aabọ, ki wọn o to da awọn ọdọ lohun. 7. Dandan ni wiwọ ibomu-bo ẹnu nipinlẹ naa. Awọn ọlọkọ eero si gbọdọ tẹle ilana ijina sira ẹni. Ṣugbọn ṣa, Gomina Sanwo-Olu sọ pe o ṣeeṣe ki isede miran tun waye, ti awọn araalu ko ba tẹle awọn ilana naa. Yàtọ̀ si aríwo tó ń tàn ká pé gómínà ìpínlẹ̀ Kwara tí paṣẹ pé ki wọ́n fún awakọ̀ tó wà nínú fọ́rán kan to fójú hàn lórí ayélujára níbi ti wọ́n ti n gbé ènìyàn kan sí inú ọkọ pàjáwìrì aláàrùn Covid-19 níwèé ìdádúro, Kọmísọ́nà fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Kwara Raji Razaq ni ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Raji Razaq ní wọ́n kan yọ awakọ̀ náà kúrò lára àwọn to n mójútó àwọn alárùn coronavirus ni, nítorí pé ó kùna láti pa àwọn ilànà tóyẹ ki o tẹ̀lé mọ́. Ó ní ọkùnrin ti wọ́n lọ gbé òun pẹ̀lú kìí ṣe àláàrùn Coronavirus, ó sì ti wà ní àkàtà ìjọba fún ìtọ́jú báyìí. Kọmísọ́nà ní gbogbo àwọn ọgálọ́gàá ilé iṣẹ́ náà to fi mọ akọwé agba ilé iṣẹ́ iléra to pàṣẹ fun awakọ̀ náà láti lọ gbé ẹni náà ni wọ́n ti gba iwé ìbáwí. Alhaji Razaq ni ìpàpara ni awakọ̀ náà fi bá iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ nítorí pé ó yẹ kí ó dúró de àwọn ti yoo gbé aṣọ ìdáàbò tó yẹ kí o wọ̀ wá, súgbọ́n ko fi àrà balẹ̀ Kíni ìlànà tó tọ́ láti gbé aláàrùn Covid-19 nílé wọn Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Kọmísọnà ní tí wọ́n ba ti pé ilé iṣẹ́ ètò ilera bẹ́ẹ̀, ọ̀dọ̀ ọ̀gá àgbà ni ìpè náà yóò dé sí ti yóò si pàsẹ fún àwọn to wà ni ìdí, ètò pàjáwìrì láti lọ́ṣe iṣẹ́ wọn. Lórí ìtàkùn ayélujára àjọ to n gbógunti ààrùn Coronavirus ni Naijira NCDC náà, wọ́n sàlàyé àwọn ìlànà ti àwọn elétò ààbò àti ará ilú gbọdọ̀ mọ̀ ti wọ́n bá ri ẹni tó ni ààrùn Coronavirus. * O ṣe pàtàkì láti mọ àwọn ibi ìtọjú to wà ni àyíka ní ìpińlẹ̀ tàbí ni agbègbè wọ́n * Àwọn elétò ìlera ti gbọdọ̀ kọ́kọ́ lọ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bi a ṣe n tọ́jú àjàkálẹ̀ ààrùn ti wọ́n pè ni (Infection, Prevention, And Control IPC). * Gbogbo òṣìṣẹ́ tí yóò ba kójú àláàrùn Covid-19 gbọdọ̀ wọ aṣọ ìdáàbò (PPE), ìbòmú, ìbọ̀wọ́, awòojú àti fìlà * Ní kété ti òṣìṣẹ́ ìlera bá ti gbé aláàrùn coronavirus tan, o ṣe pàtàkì láti fi àwọn kẹmika apakòkòrò tọ́jú gbogbo ǹkan ti ẹni náà wọ̀ kí o to kúrò ní ilé ìwòsàn. Sáájú ní àkọ̀wé gómìnà Kwara Rafiu Ajakaye ti fi àtẹjáde kan síta pé gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara Abdulrazaq Abdulraman ti pàṣẹ pé kí wọ́n fún àwakọ̀ náà ni iwé ìdádúró. Sùgbọ́n nígbà ti BBC padà pèé ló ní, wọ́n kan yọọ́ kúrò ni ẹ̀ka Covid -19 ní kìíṣe pé wọ́n yọọ́ lẹ́nu iṣẹ́ Atẹ́gùn òjò rán ọ̀pọ̀ lóko àdánù nílùú Ìbàdàn, aráàlú gbarata Ibadan rainstorm: Awọn olugbe ilu Ibadan gbarata lori awọn ile ti atẹgun ojo ṣidanu Awọn olugbe agbegbe Joyce B ni ilu Ibadan ti bẹrẹ sini ke irora lẹyin ti ojo to fi iṣeju marundinlaadọta rọ lopin ọṣẹ ṣe akoba fun awọn ile kan. Ninu itakurọsọ pẹlu ikọ BBC Yoruba, ọkan lara awọn ti o fi ara gba iṣẹlẹ naa, arakunrin Kayọde Popoọla ṣe alaya wi pe iru iṣẹlẹ bẹẹ ko ṣẹlẹ ri lati nnkan bii ogun ọdun sẹyin ti oun ati ayarẹ ti ya ile ti wọn fi da ile ẹkọ silẹ fun awọn akẹkọ to n bẹ ni agbegbe naa. O ni oun n wẹ lọwọ ni nigba ti ipe pajawiri kan wọle wi pe atẹgun ojo ti ṣi paanu ile lọ ti o si rọ lu ile alaja kan to n bẹ ni iwaju ibi ti wọn fi n ṣe ile ẹkọ. O ni, "Inu ile mi ti mo n gbe ni mo wa, mo n wẹ lọwọ ni gbogbo inu ile bẹrẹ sini mi gbugbugbu. Bi mo ṣe jade nile iwẹ mo rii pe yara mi ti n jo. Yara mi o jo ri, yara awọn ọmọ mi naa bakan naa. Iyẹn ni a n mojuto lọwọ mo n pe Ọlọrun pe aanu, aanu o. Lojiji ni ẹrọ ibanisọrọ mi dun, ọkan ni ninu awọn olukọ wa lo pe mo ba gbe ipe rẹ. Jọkẹ ki lo ṣe ẹ? Daddy atẹgun ti gbe gbogbo paanu o..." Popoọla ni iye owo ti yoo ṣe atunṣe ile ẹkọ naa ko di ni milliọnu meji naira, bẹẹ sini awọn to ya ile igbe lo jẹ gbese nitori baba to ni ile ti darugbo. O ra ọwọ ẹbẹ si ijọba ati awọn ẹlẹyin ju aanu lati ṣe iranlọwọ fun wọn lasiko yii. Gbogbo paanu ti atẹgun ojo ṣi danu ni awọn to n gbe awọn ile naa ti n gbiyanju lati kojọpọ si ẹgbẹ kan lasiko ti ikọ iroyin BBC Yoruba ṣe abẹwo si agbegbe kan.Lọkọọkan-ejeeji sini wọn duro gẹgẹ bi wọn ṣe n wo awọn ile naa pẹlu iyalẹnu. Eeyan ẹrin ọtọọtọ lo padanu ẹmi wọn ti ọgọrọ awọn eeyan mii si fi ara pa ninu ijamba ọkọ to waye nilu Ogbomoṣọ lọsan ọjọ ẹti.Ni agbegbe Apake lopopona marosẹ Ogbomọṣọ si Ilọrin atijọ ni ọkọ akẹru kan ti sa wọ ibi ti awọn ero ọkọ ati ọlọkada korajọpọ si. O ṣoju mi koro ṣe alaye fun awọn oniroyin pe eeyan mẹrin lo ku loju ẹsẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ko awọn ti o fi ara pa lọ si ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun Oyinbo, LAUTECHTH to n bẹ niluu Ogbomọṣọ.Iroyin sọ wi pe ẹkun ariwa ni ọkọ naa n ri irinajo lọ ki o to di wi pe o padanu ijanu ọkọ lasiko to n sa fun awọn ẹṣọ aabo oju popo niluu Ogbọmọṣọ, ṣugbọn adari ẹṣọ aabo oju popo to n bẹ ni agbegbe naa, Bọlade Olugbẹsan sọ wi pe irọ to jina si ọọtọ ni ẹsun naa. O ni ko si oṣiṣẹ ẹṣọ aabo pupo ni ibi ti ijamba naa ti ṣẹlẹ.O ṣoju mi koro mii ti o ba awọn oniroyin sọrọ ṣe alaye wi pe ọlọkada ni awọn eeyan mẹrẹẹrin to padanu ẹmi wọn sinu ijamba naa.Lasiko ti a ṣe akojọpọ iroyin yii, awọn osiṣẹ aabo duro wamuwamu si ofisi ẹṣọ aabo oju to n bẹ ni agbegbe 'High School' niluu Ogbomọṣọ lati dena akolu awọn ara ilu to n fapajanu nitori ijamba naa. Mẹrin ninu awọn eeyan mọkanla to n ti ipinlẹ Sokoto bọ ṣugbọn ti awọn agbofinro mu lẹnu ibode ipinlẹ Oyo si Osun lo ni arun Coronavirus. Ẹni to n risi iṣẹlẹ naa, Taiwo Ladipo lo fi ọrọ ọhun lede fun awọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun. O ni awọn mẹrin naa ti wa ni ile iwosan ti wọn ya sọtọ fun awọn to ni arun Covid-19, eyi to wa ni Olodo. Lẹyin itakurọsọ pẹlu awọn arinrin ajo naa, Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde sọ pe oun ko ni yọnda wọn fun ijọba ipinlẹ Sokoto, ayafi ti wọn ba kọkọ ṣayẹwo arun Coronavirus fun wọn. Iye awọn to ti lugbadi arun naa nipinlẹ Oyo lọwọ yii jẹ mọkandinlogoji, ti mejidinlọgbọn ninu wọn si n gba itọju lọwọ. Bo tilẹ jẹ pe awọn mẹsan an ti ri iwosan, awọn kan ti jẹ Ọlọrun nipe nipe nitori arun naa. Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe ko si ẹni kankan to tii ni arun Coronavirus nipinlẹ naa, ati pe oun ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣawari awọn eeyan to ṣalabapade ẹni ti wọn fura si pe o ṣeṣe ko ti ko arun naa wọ ipinlẹ ọhun. Kọmiṣọna eto ilera, Bashir Bello ni ijọbaa ti ṣayẹwo ẹni kan to ṣẹṣẹ de lati ilẹ Gẹẹsi, ti wọn si ti fi ayẹwo naa ranṣẹ si yara ayẹwọ to wa ni fasiti ẹkọṣẹ iṣegun to wa ni ilu Eko, LUTH. O ni lọwọ yii, oun ko tii le fidi rẹ mulẹ pe ẹnikẹni ti lugbadi arun naa nipinlẹ Oyo titi di igba ti esi ayẹwo naa yoo jade. Bello sọ pe ijọba ipinlẹ naa mọ pe ẹni to ko arun Coronavirus wọ ipinlẹ Ekiti lo akoko diẹ nilu Ibadan. O ni ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Oyo ti n gbaradi lati koju arun ọhun lati igba to ti ṣẹyọ lorilẹ-ede Naijiria. Bello tẹsiwaju pe "Bo tilẹ jẹ pe arun yii ti n peleke si ni Naijiria, ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ wa n ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe arun naa ko si ni ipinlẹ Oyo." Bello wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati ma foya nitori arun naa, ṣugbọn ki wọn ma ṣe awọn ohun to le mu arun jina si ayika wọn, bii wiwa ni nkan bii iwọn ẹsẹ bata mẹfa si awọn elomiran ati ṣisṣọra fun ibi ti ọpọ eeyan ba korajọpọ si. Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kán Seyi Makinde níkòó fún ìgbàlejò ìpàdé ìtagbangba PDP níbàdàn lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn coronavirus Ọpọ lo ti n bu ẹnu atẹ lu bi Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti ṣe ipade itagbangbe oṣelu ẹgbẹ oṣelu PDP niluu Ibadan l'Ọjọru, bo tilẹ jẹ wi pe ibẹrubojo awọn arun coronavirus wa nita. Nigba to n sọrọ nibi ipade ọhun to waye ni gbọngan Mapo, Makinde ni apẹrẹ wi pe ẹgbẹ oṣelu PDP ti bẹrẹ si ni gbori soke ni bi Gomina ipinlẹ Osun tẹlẹ, Olagunsoye Oyinlola ati awọn alatilẹyin rẹ ṣe pada sinu ẹgbẹ naa. Igbakeji gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Taofeek Arapaja, sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun ariwa Oyo tẹlẹ, Dokita Gbenga Babalola atawọn eekan inu ẹgbẹ oṣelu ADC to fi mọ oludije fun ipo gomina nipinlẹ Osun, Alhaji Fatai Akinbade lo darapọ mọ PDP nibi ipade ọhun. Bakan naa lawọn eekan inu ẹgbẹ oṣelu ADP ati ZLP darapọ mọ PDP nibi ipadae itagbangba naa ti wọn pe ni ipade iṣọkan ni Ibadan. ''Ipade yii jẹ ibẹrẹ iṣọkan apa iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria, ti a ba si ti wa ni iṣọkan lapa iwọ oorun gusu, Naijiria naa ti wa ni iṣọkan niyẹn,'' Gomina Makinde lo sọ bẹẹ. Makinde ni ''awọn eeyan kan ni ko yẹ ki PDP ṣe iru ipade itagbangba bayii lasiko ti coronavirus n tankalẹ yii, ṣugbọn ọkan lara awọn olori wọn lo sọ pe arun coronavirus ti wọ inu ẹgbẹ wọn, amọ awa mọ pe ko si ninu ẹgbẹ ti wa.'' Ninu ọrọ tiẹ nibi ipade naa, Oyinlola sọ pe asiko ti to lati ṣe atunto orilẹede Naijiria, o ni itanjẹ ẹgbẹ APC ti to gẹẹ. O rọ awọn ọmọ ẹgbẹ PDP lati fi ọgbọn yanju ọrọ to ba wa laarin wọn ki iṣokan le wa ninu ẹgbẹ. ''Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ lọ sí ibi ìpàdé PDP ní Ibadan, ẹ lọ yara yín sọ́tọ̀ fún àyẹ̀wò coronavirus'' Ọgọrọ eeyan lo dẹnu bo Gomina Seyi Makinde lori ayelujara lẹyin to ṣagbatẹru ipade itagbangba ẹgbẹ oṣelu PDP niluu Ibadan l'Ọjọru. Ohun ti ọpọ n sọ nipe kii ṣe akoko yii ti ibẹru-bojo ajankalẹ arun coronavirus wa nita lo yẹ ki Makinde ṣe iru ipade bẹẹ. Ibrahim Lawal Esq ṣapejuwe ipade itagbangba PDP bi igbesẹ omugọ ti ko mu ọgbọn wa rara. Ibeere ni @AbdulMahmud01 n beere ni tirẹ, o ni ''kinni o n ṣe wa gan an? O sọ pe o ṣeni laanu pe ko si ẹnikan to ronu pe iru ipade itagbangba yii le ṣakoba fun eto ilera araalu pẹlu bi arun covid-19 sẹ wa nita bayii. @Lucasscot_101 ṣalaye ni tiẹ wi pe ẹgbẹ oṣelu APC lo kọkọ bẹrẹ iwa aṣiwere tawọn eeyan si ro pe ko si were to le ju iyẹn lọ. Amọ o ni o ṣeni laanu pe iwa aṣiwere ti ẹgbẹ oṣelu PDP gan wa ju ti APC lọ. O pari rẹ bayii pe ko si ẹni ti ori rẹ pe ninu awọn ẹgbẹ mejeeji. Adeola @Harrdehy fi igbe bọnu ni tiẹ, o ni ẹnikẹni to ba kopa ninu ipade itagangba ẹgbẹ osẹlu PDP gbọdọ ya ara rẹ sọtọ fun ayẹwo arun coronavirus. Ọgọrọ eeyan lo fẹnu ko pe igbesẹ ẹgbẹ osẹlu PDP lati ṣe ipade naa kudiẹ kaato. Amọ ninu gbogbo eyi, ero Olamide Abimbola yatọ ni tiẹ. O ni aṣiwere ni gbogbo awọn to n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ APC ti wọn n sọ oko ọrọ si PDP nitori ipade itagbangba ti wọn ṣe ni Ibadan. Abimbola ni ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe iru ipade itagbangba ti ko waye ri ninu iwe itan. O rọ awọn to n bu ẹgbẹ naa loju opo Twitter pe ki wọn ronu si ọrọ naa daadaa ki wọn to maa sọrọ loju opo Twitter. | Coronavirus treatments: Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá pàṣẹ pé kò gbọdọ̀ sí ìdádúró fún àwọn tí iṣẹ́ wọn ṣe kókó lásíkò ìséde Ẹgbẹ awọn dokita onimọ iṣegun oyinbo ni Naijiria ti fagile iyanṣẹlodi ti wọn bẹrẹ, nitori bi awọn ọlọpaa ṣe fiyajẹ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn kan lasiko isede coronavirus. Lara oun ti awọn dokita naa tọka si nipe ileeṣẹ ọlọpaa n da awọn ọmọ ẹgbẹ wọn duro, eyi ti ko yọ awọn ọkọ to n gbe alaisan silẹ. Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi sita, wọn ni ki awọn dokita o pada si ẹnu'ṣẹ wọn laago mẹfa irọlẹ oni. Iyanṣẹlodi naa ko pe wakati mejila ti wọn fi kede pe awọn ti fagile. Ọjọru ni wọn bẹrẹ iyanṣẹlodi naa, ti wọn si s pe yoo wa titi di igba ti ijọba yoo fopin si ifiyajẹni ti awọn ọlọpaa n ṣe si awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lasiko ofin Konile-o-gbele. Ninu atẹjade ti ẹgbẹ ọhun fi sita ni wọn ti fikun pe awọn ọlọpaa tilẹ n ti wọn mọle ni aini idi. Ṣugbọn ṣa, Ọga Agba Ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Muhammed Adamu paapa ti fi aṣẹ tuntun sita nipa ofin konile o-gbele kaakiri orilẹede Naijiria. Ko din ni aadọta awọn dokita , oniroyin atawọn oṣiṣẹ ẹka to ṣe koko miran lasiko ajakalẹ arun coronavirus yii ni awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti fi panpaẹ ofin mu bayii lọjọ Iṣẹgun ni ibamu pẹlu aṣẹ kan ti ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria pa. Ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹrin ni aarẹ Muhammadu Buhari paṣẹ konile o gbele eleyii to de igbokegbodo ọkọ laarin agogo mẹjọ alẹ si agogo mẹfa owurọ gẹgẹ bi ara ọna lati dena itankalẹ ajakalẹ orun COVID-19. Amọṣa aarẹ ko ṣai ṣe gafara fun awọn oṣiṣẹ ti iṣẹ wọn jẹ koṣemaani lasiko naa bii awọn oṣiṣẹ eto ilera, akọroyin ati bẹẹbẹl lọ. Ni ọjọ Iṣẹgun ni ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria ṣe ipade ori ayelujara pẹlu awọn lọgalọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa lorilẹ€de Naijiria nibi to ti paṣẹ fun wọn lati tubọ rii pe aṣẹ konile o gbele naa fẹsẹmulẹ sii ti wọn si ni o paṣẹ pe ki wọn maa fi panpẹ ofin mu ẹnikẹni ti irinkerindo rẹ ba ti kọja agogo mẹjọ alẹ. Lagbegbe Alausa ni ilu Eko, gbogbo awọn dokita ati akọroyin to n bọ lati ibi iṣẹ ni awsn ọlọpaa ko da satimọle ti wọn si gbẹsẹle ọkọ wọn. Iroyin taa gbọ ni pe awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ti aarẹ gbe kalẹ lori kikoju arun coronavirus, PTF lo wa kan si ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria ki o to paṣẹ ki wọn tu wọn silẹ lẹyin ti wọn ti lo bii wakati meji lagọ ọlọpaa. Ijọba ipinlẹ Eko ti n gbeero lati fi opin si isede coronavirus patapata, ṣugbọn diẹdiẹ ni yoo bẹrẹ. Gomina Babajide Sanwo-Olu lo kede awọn ilana tuntun yii, pẹlu boṣe jẹ pe ipinlẹ Eko ni aarun coronavirus pọ si julọ ni Naijiria. Ọsẹ keji ti ijọba dẹ isede lo n pari lọ bayii, ṣugbọn gomina sọ pe ọsẹ mẹfa ni yoo gba. 1. Register-to-Open - Eyi tumọ si pe ijọba yoo kọkọ ṣe ayẹwo ile ijọsin, ileeṣẹ, tabi ile itaja to ba fẹ ẹ bẹrẹ iṣẹ pada. 2. Lẹyin ayẹwo naa, ileeṣẹ, ile ijọsin, tabi ile itaja bẹ ẹ yoo gba iwe ẹri pe o pa ilana ati ofin ti ijọba gbe kalẹ lati fi opin si Covid-19. 3. Ijọba ko ti i sọ ọjọ ti awọn eeyan wọn yii yoo pada bẹrẹ iṣẹ wọn, lẹyin ayẹwo naa, ṣugbọn o sọ pe ki awọn to ni ileeṣẹ naa mura silẹ lati tẹle ilana tuntun naa, nitori pe coronavirus ti mu ayipada ba ayika wa. 4. Awọn ti ilana tuntun naa kan ni ṣọọṣi, mọṣalaaṣi, gbọngan ayẹyẹ, ile itaja igbalode nla, gbọngan sinima, ati awọn ibi igbafẹ. 5. Awọn nkan ti ijọba yoo yẹwo kii wọn o to o fun wọn ni iwe ẹri ni, ilana ijina sira ẹni ti wọn ti gbe kalẹ, ati fun imọtoto. Awọn nkan wọnyii ni yoo si sọ boya awọn ṣọọṣi ati mọṣalaaṣi naa yoo ṣi pada. 6. Ijọba yoo paṣẹ fun awọn banki, ati ọja lati maa da awọn onibara to jẹ agbalagba lohun laarin aago mẹsan aarọ si mẹwa aabọ, ki wọn o to da awọn ọdọ lohun. 7. Dandan ni wiwọ ibomu-bo ẹnu nipinlẹ naa. Awọn ọlọkọ eero si gbọdọ tẹle ilana ijina sira ẹni. Ṣugbọn ṣa, Gomina Sanwo-Olu sọ pe o ṣeeṣe ki isede miran tun waye, ti awọn araalu ko ba tẹle awọn ilana naa. Yàtọ̀ si aríwo tó ń tàn ká pé gómínà ìpínlẹ̀ Kwara tí paṣẹ pé ki wọ́n fún awakọ̀ tó wà nínú fọ́rán kan to fójú hàn lórí ayélujára níbi ti wọ́n ti n gbé ènìyàn kan sí inú ọkọ pàjáwìrì aláàrùn Covid-19 níwèé ìdádúro, Kọmísọ́nà fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Kwara Raji Razaq ni ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Raji Razaq ní wọ́n kan yọ awakọ̀ náà kúrò lára àwọn to n mójútó àwọn alárùn coronavirus ni, nítorí pé ó kùna láti pa àwọn ilànà tóyẹ ki o tẹ̀lé mọ́. Ó ní ọkùnrin ti wọ́n lọ gbé òun pẹ̀lú kìí ṣe àláàrùn Coronavirus, ó sì ti wà ní àkàtà ìjọba fún ìtọ́jú báyìí. Kọmísọ́nà ní gbogbo àwọn ọgálọ́gàá ilé iṣẹ́ náà to fi mọ akọwé agba ilé iṣẹ́ iléra to pàṣẹ fun awakọ̀ náà láti lọ gbé ẹni náà ni wọ́n ti gba iwé ìbáwí. Alhaji Razaq ni ìpàpara ni awakọ̀ náà fi bá iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ nítorí pé ó yẹ kí ó dúró de àwọn ti yoo gbé aṣọ ìdáàbò tó yẹ kí o wọ̀ wá, súgbọ́n ko fi àrà balẹ̀ Kíni ìlànà tó tọ́ láti gbé aláàrùn Covid-19 nílé wọn Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Kọmísọnà ní tí wọ́n ba ti pé ilé iṣẹ́ ètò ilera bẹ́ẹ̀, ọ̀dọ̀ ọ̀gá àgbà ni ìpè náà yóò dé sí ti yóò si pàsẹ fún àwọn to wà ni ìdí, ètò pàjáwìrì láti lọ́ṣe iṣẹ́ wọn. Lórí ìtàkùn ayélujára àjọ to n gbógunti ààrùn Coronavirus ni Naijira NCDC náà, wọ́n sàlàyé àwọn ìlànà ti àwọn elétò ààbò àti ará ilú gbọdọ̀ mọ̀ ti wọ́n bá ri ẹni tó ni ààrùn Coronavirus. * O ṣe pàtàkì láti mọ àwọn ibi ìtọjú to wà ni àyíka ní ìpińlẹ̀ tàbí ni agbègbè wọ́n * Àwọn elétò ìlera ti gbọdọ̀ kọ́kọ́ lọ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bi a ṣe n tọ́jú àjàkálẹ̀ ààrùn ti wọ́n pè ni (Infection, Prevention, And Control IPC). * Gbogbo òṣìṣẹ́ tí yóò ba kójú àláàrùn Covid-19 gbọdọ̀ wọ aṣọ ìdáàbò (PPE), ìbòmú, ìbọ̀wọ́, awòojú àti fìlà * Ní kété ti òṣìṣẹ́ ìlera bá ti gbé aláàrùn coronavirus tan, o ṣe pàtàkì láti fi àwọn kẹmika apakòkòrò tọ́jú gbogbo ǹkan ti ẹni náà wọ̀ kí o to kúrò ní ilé ìwòsàn. Sáájú ní àkọ̀wé gómìnà Kwara Rafiu Ajakaye ti fi àtẹjáde kan síta pé gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara Abdulrazaq Abdulraman ti pàṣẹ pé kí wọ́n fún àwakọ̀ náà ni iwé ìdádúró. Sùgbọ́n nígbà ti BBC padà pèé ló ní, wọ́n kan yọọ́ kúrò ni ẹ̀ka Covid -19 ní kìíṣe pé wọ́n yọọ́ lẹ́nu iṣẹ́ Atẹ́gùn òjò rán ọ̀pọ̀ lóko àdánù nílùú Ìbàdàn, aráàlú gbarata Ibadan rainstorm: Awọn olugbe ilu Ibadan gbarata lori awọn ile ti atẹgun ojo ṣidanu Awọn olugbe agbegbe Joyce B ni ilu Ibadan ti bẹrẹ sini ke irora lẹyin ti ojo to fi iṣeju marundinlaadọta rọ lopin ọṣẹ ṣe akoba fun awọn ile kan. Ninu itakurọsọ pẹlu ikọ BBC Yoruba, ọkan lara awọn ti o fi ara gba iṣẹlẹ naa, arakunrin Kayọde Popoọla ṣe alaya wi pe iru iṣẹlẹ bẹẹ ko ṣẹlẹ ri lati nnkan bii ogun ọdun sẹyin ti oun ati ayarẹ ti ya ile ti wọn fi da ile ẹkọ silẹ fun awọn akẹkọ to n bẹ ni agbegbe naa. O ni oun n wẹ lọwọ ni nigba ti ipe pajawiri kan wọle wi pe atẹgun ojo ti ṣi paanu ile lọ ti o si rọ lu ile alaja kan to n bẹ ni iwaju ibi ti wọn fi n ṣe ile ẹkọ. O ni, "Inu ile mi ti mo n gbe ni mo wa, mo n wẹ lọwọ ni gbogbo inu ile bẹrẹ sini mi gbugbugbu. Bi mo ṣe jade nile iwẹ mo rii pe yara mi ti n jo. Yara mi o jo ri, yara awọn ọmọ mi naa bakan naa. Iyẹn ni a n mojuto lọwọ mo n pe Ọlọrun pe aanu, aanu o. Lojiji ni ẹrọ ibanisọrọ mi dun, ọkan ni ninu awọn olukọ wa lo pe mo ba gbe ipe rẹ. Jọkẹ ki lo ṣe ẹ? Daddy atẹgun ti gbe gbogbo paanu o..." Popoọla ni iye owo ti yoo ṣe atunṣe ile ẹkọ naa ko di ni milliọnu meji naira, bẹẹ sini awọn to ya ile igbe lo jẹ gbese nitori baba to ni ile ti darugbo. O ra ọwọ ẹbẹ si ijọba ati awọn ẹlẹyin ju aanu lati ṣe iranlọwọ fun wọn lasiko yii. Gbogbo paanu ti atẹgun ojo ṣi danu ni awọn to n gbe awọn ile naa ti n gbiyanju lati kojọpọ si ẹgbẹ kan lasiko ti ikọ iroyin BBC Yoruba ṣe abẹwo si agbegbe kan.Lọkọọkan-ejeeji sini wọn duro gẹgẹ bi wọn ṣe n wo awọn ile naa pẹlu iyalẹnu. Eeyan ẹrin ọtọọtọ lo padanu ẹmi wọn ti ọgọrọ awọn eeyan mii si fi ara pa ninu ijamba ọkọ to waye nilu Ogbomoṣọ lọsan ọjọ ẹti.Ni agbegbe Apake lopopona marosẹ Ogbomọṣọ si Ilọrin atijọ ni ọkọ akẹru kan ti sa wọ ibi ti awọn ero ọkọ ati ọlọkada korajọpọ si. O ṣoju mi koro ṣe alaye fun awọn oniroyin pe eeyan mẹrin lo ku loju ẹsẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ko awọn ti o fi ara pa lọ si ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun Oyinbo, LAUTECHTH to n bẹ niluu Ogbomọṣọ.Iroyin sọ wi pe ẹkun ariwa ni ọkọ naa n ri irinajo lọ ki o to di wi pe o padanu ijanu ọkọ lasiko to n sa fun awọn ẹṣọ aabo oju popo niluu Ogbọmọṣọ, ṣugbọn adari ẹṣọ aabo oju popo to n bẹ ni agbegbe naa, Bọlade Olugbẹsan sọ wi pe irọ to jina si ọọtọ ni ẹsun naa. O ni ko si oṣiṣẹ ẹṣọ aabo pupo ni ibi ti ijamba naa ti ṣẹlẹ.O ṣoju mi koro mii ti o ba awọn oniroyin sọrọ ṣe alaye wi pe ọlọkada ni awọn eeyan mẹrẹẹrin to padanu ẹmi wọn sinu ijamba naa.Lasiko ti a ṣe akojọpọ iroyin yii, awọn osiṣẹ aabo duro wamuwamu si ofisi ẹṣọ aabo oju to n bẹ ni agbegbe 'High School' niluu Ogbomọṣọ lati dena akolu awọn ara ilu to n fapajanu nitori ijamba naa. Mẹrin ninu awọn eeyan mọkanla to n ti ipinlẹ Sokoto bọ ṣugbọn ti awọn agbofinro mu lẹnu ibode ipinlẹ Oyo si Osun lo ni arun Coronavirus. Ẹni to n risi iṣẹlẹ naa, Taiwo Ladipo lo fi ọrọ ọhun lede fun awọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun. O ni awọn mẹrin naa ti wa ni ile iwosan ti wọn ya sọtọ fun awọn to ni arun Covid-19, eyi to wa ni Olodo. Lẹyin itakurọsọ pẹlu awọn arinrin ajo naa, Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde sọ pe oun ko ni yọnda wọn fun ijọba ipinlẹ Sokoto, ayafi ti wọn ba kọkọ ṣayẹwo arun Coronavirus fun wọn. Iye awọn to ti lugbadi arun naa nipinlẹ Oyo lọwọ yii jẹ mọkandinlogoji, ti mejidinlọgbọn ninu wọn si n gba itọju lọwọ. Bo tilẹ jẹ pe awọn mẹsan an ti ri iwosan, awọn kan ti jẹ Ọlọrun nipe nipe nitori arun naa. Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe ko si ẹni kankan to tii ni arun Coronavirus nipinlẹ naa, ati pe oun ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣawari awọn eeyan to ṣalabapade ẹni ti wọn fura si pe o ṣeṣe ko ti ko arun naa wọ ipinlẹ ọhun. Kọmiṣọna eto ilera, Bashir Bello ni ijọbaa ti ṣayẹwo ẹni kan to ṣẹṣẹ de lati ilẹ Gẹẹsi, ti wọn si ti fi ayẹwo naa ranṣẹ si yara ayẹwọ to wa ni fasiti ẹkọṣẹ iṣegun to wa ni ilu Eko, LUTH. O ni lọwọ yii, oun ko tii le fidi rẹ mulẹ pe ẹnikẹni ti lugbadi arun naa nipinlẹ Oyo titi di igba ti esi ayẹwo naa yoo jade. Bello sọ pe ijọba ipinlẹ naa mọ pe ẹni to ko arun Coronavirus wọ ipinlẹ Ekiti lo akoko diẹ nilu Ibadan. O ni ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Oyo ti n gbaradi lati koju arun ọhun lati igba to ti ṣẹyọ lorilẹ-ede Naijiria. Bello tẹsiwaju pe "Bo tilẹ jẹ pe arun yii ti n peleke si ni Naijiria, ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ wa n ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe arun naa ko si ni ipinlẹ Oyo." Bello wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati ma foya nitori arun naa, ṣugbọn ki wọn ma ṣe awọn ohun to le mu arun jina si ayika wọn, bii wiwa ni nkan bii iwọn ẹsẹ bata mẹfa si awọn elomiran ati ṣisṣọra fun ibi ti ọpọ eeyan ba korajọpọ si. Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kán Seyi Makinde níkòó fún ìgbàlejò ìpàdé ìtagbangba PDP níbàdàn lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn coronavirus Ọpọ lo ti n bu ẹnu atẹ lu bi Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti ṣe ipade itagbangbe oṣelu ẹgbẹ oṣelu PDP niluu Ibadan l'Ọjọru, bo tilẹ jẹ wi pe ibẹrubojo awọn arun coronavirus wa nita. Nigba to n sọrọ nibi ipade ọhun to waye ni gbọngan Mapo, Makinde ni apẹrẹ wi pe ẹgbẹ oṣelu PDP ti bẹrẹ si ni gbori soke ni bi Gomina ipinlẹ Osun tẹlẹ, Olagunsoye Oyinlola ati awọn alatilẹyin rẹ ṣe pada sinu ẹgbẹ naa. Igbakeji gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Taofeek Arapaja, sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun ariwa Oyo tẹlẹ, Dokita Gbenga Babalola atawọn eekan inu ẹgbẹ oṣelu ADC to fi mọ oludije fun ipo gomina nipinlẹ Osun, Alhaji Fatai Akinbade lo darapọ mọ PDP nibi ipade ọhun. Bakan naa lawọn eekan inu ẹgbẹ oṣelu ADP ati ZLP darapọ mọ PDP nibi ipadae itagbangba naa ti wọn pe ni ipade iṣọkan ni Ibadan. ''Ipade yii jẹ ibẹrẹ iṣọkan apa iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria, ti a ba si ti wa ni iṣọkan lapa iwọ oorun gusu, Naijiria naa ti wa ni iṣọkan niyẹn,'' Gomina Makinde lo sọ bẹẹ. Makinde ni ''awọn eeyan kan ni ko yẹ ki PDP ṣe iru ipade itagbangba bayii lasiko ti coronavirus n tankalẹ yii, ṣugbọn ọkan lara awọn olori wọn lo sọ pe arun coronavirus ti wọ inu ẹgbẹ wọn, amọ awa mọ pe ko si ninu ẹgbẹ ti wa.'' Ninu ọrọ tiẹ nibi ipade naa, Oyinlola sọ pe asiko ti to lati ṣe atunto orilẹede Naijiria, o ni itanjẹ ẹgbẹ APC ti to gẹẹ. O rọ awọn ọmọ ẹgbẹ PDP lati fi ọgbọn yanju ọrọ to ba wa laarin wọn ki iṣokan le wa ninu ẹgbẹ. ''Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ lọ sí ibi ìpàdé PDP ní Ibadan, ẹ lọ yara yín sọ́tọ̀ fún àyẹ̀wò coronavirus'' Ọgọrọ eeyan lo dẹnu bo Gomina Seyi Makinde lori ayelujara lẹyin to ṣagbatẹru ipade itagbangba ẹgbẹ oṣelu PDP niluu Ibadan l'Ọjọru. Ohun ti ọpọ n sọ nipe kii ṣe akoko yii ti ibẹru-bojo ajankalẹ arun coronavirus wa nita lo yẹ ki Makinde ṣe iru ipade bẹẹ. Ibrahim Lawal Esq ṣapejuwe ipade itagbangba PDP bi igbesẹ omugọ ti ko mu ọgbọn wa rara. Ibeere ni @AbdulMahmud01 n beere ni tirẹ, o ni ''kinni o n ṣe wa gan an? O sọ pe o ṣeni laanu pe ko si ẹnikan to ronu pe iru ipade itagbangba yii le ṣakoba fun eto ilera araalu pẹlu bi arun covid-19 sẹ wa nita bayii. @Lucasscot_101 ṣalaye ni tiẹ wi pe ẹgbẹ oṣelu APC lo kọkọ bẹrẹ iwa aṣiwere tawọn eeyan si ro pe ko si were to le ju iyẹn lọ. Amọ o ni o ṣeni laanu pe iwa aṣiwere ti ẹgbẹ oṣelu PDP gan wa ju ti APC lọ. O pari rẹ bayii pe ko si ẹni ti ori rẹ pe ninu awọn ẹgbẹ mejeeji. Adeola @Harrdehy fi igbe bọnu ni tiẹ, o ni ẹnikẹni to ba kopa ninu ipade itagangba ẹgbẹ osẹlu PDP gbọdọ ya ara rẹ sọtọ fun ayẹwo arun coronavirus. Ọgọrọ eeyan lo fẹnu ko pe igbesẹ ẹgbẹ osẹlu PDP lati ṣe ipade naa kudiẹ kaato. Amọ ninu gbogbo eyi, ero Olamide Abimbola yatọ ni tiẹ. O ni aṣiwere ni gbogbo awọn to n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ APC ti wọn n sọ oko ọrọ si PDP nitori ipade itagbangba ti wọn ṣe ni Ibadan. Abimbola ni ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe iru ipade itagbangba ti ko waye ri ninu iwe itan. O rọ awọn to n bu ẹgbẹ naa loju opo Twitter pe ki wọn ronu si ọrọ naa daadaa ki wọn to maa sọrọ loju opo Twitter. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-51956853 |
2health
| Breast milk sale: Orí kó obìnrin 115 yọ lọ́wọ́ àwọn tó ń gba omi ọyàn wọn l'Abuja | Awọn alaṣẹ tọrọ kan ti da si ọrọ awọn iyalọmọ marunlelaadọfa nilu Abuja ti awọn kan n gba omi ọmu wọn lojoojumọ ti wọn si n fi ṣe oniruuru nkan afi omi ọmu ṣe bii wara, bọta ati miliiki mimu. Ọpọlọpọ awọn iyalọmọ ti wọn n lo fun iṣẹ laabi yii lo jẹ ọdọbinrin bii ọmọ ọdun mẹrindinlogun ti eyi to dagba ju ninu wọn si jẹ ẹni ọdun mejilelogun ti iroyin si kan pe poora lawujọ ibi ti wọn n gbe. Awọn ọlọpaa lo fura pe awọn ajinigbe to ko wọn pamọ n ka fidio gbogbo nkan ti wọn n ṣe fun wọn lati ọdun mẹta sẹyin ti wọ́n si n gbe sori ayelujara awọn onibara wọn. Iroyin sọ pe awọn alaburu to n kore nibi ti wọn o gbin si yii maa n fipa ba awọn ọmọbinrin naa lopọ, wọn a fun wọn lóyún ni gbangba lori ayelujara idakọnkọ ti wọn ṣi pẹlu awọn onibara wọn. Bi wọn ba wa bimọ tan, wọn a bẹrẹ si ni fun omi mu wọn lojoojumọ pẹlu awọn irinṣẹ ti awọn ileeṣẹ nla nla n lo lati fi fun waraa maalu. Lori irọ ni wọn fi gbe maalu Mẹta ti iya n jẹ siwaju ọfiisi wọn nitorii bi ọlọpaa ba fẹ yọju wo nkan to n lọ nibẹ. Ọpọlọpọ ọja ti wọn maa n ko jade latinu ile iṣiṣẹ wọn ni wọn maa n ko lọ oke okun pẹlu fidio ilana ti wọn n gba fun omi ọmu lara wọn ati bi wọn ṣe n sọ ọ di odidi. Ninu ẹrọ kọmputa atawọn iwe ti wọn gba lọwọ wn ni aṣiri ti tu pe lara awọn ololufẹ wọn to maa n wo wọn lo da iléeṣẹ́ fífún omi ọyàn silẹ fun wọn. Awọn oludasilẹ wọn yii lo n san owo fun wọn pẹlu cryptocurrency. Wọn maa n san owo lati ni fidio ti wọn yoo da fi ranṣẹ si eeyan kan ṣoṣo lati wo ati bi wọn ṣe n fun omi ọmu awọn ọmọbinrin. Iroyin sọ pe nigba mii awọn eeeyan kan a diidi bere fun pe ki wọn fun ọmọbinrin kan lara wọn ni irufẹ ounjẹ kan pato jẹ looto ki wọn to fun omi ọmu rẹ bi ẹni to f ra a ṣe fẹ ati pe ninu fidio, ki ọmọbinrin naa sọ pe "omi ọmu yio, tirẹ Mr A tabi Mrs B ni". | Breast milk sale: Orí kó obìnrin 115 yọ lọ́wọ́ àwọn tó ń gba omi ọyàn wọn l'Abuja Awọn alaṣẹ tọrọ kan ti da si ọrọ awọn iyalọmọ marunlelaadọfa nilu Abuja ti awọn kan n gba omi ọmu wọn lojoojumọ ti wọn si n fi ṣe oniruuru nkan afi omi ọmu ṣe bii wara, bọta ati miliiki mimu. Ọpọlọpọ awọn iyalọmọ ti wọn n lo fun iṣẹ laabi yii lo jẹ ọdọbinrin bii ọmọ ọdun mẹrindinlogun ti eyi to dagba ju ninu wọn si jẹ ẹni ọdun mejilelogun ti iroyin si kan pe poora lawujọ ibi ti wọn n gbe. Awọn ọlọpaa lo fura pe awọn ajinigbe to ko wọn pamọ n ka fidio gbogbo nkan ti wọn n ṣe fun wọn lati ọdun mẹta sẹyin ti wọ́n si n gbe sori ayelujara awọn onibara wọn. Iroyin sọ pe awọn alaburu to n kore nibi ti wọn o gbin si yii maa n fipa ba awọn ọmọbinrin naa lopọ, wọn a fun wọn lóyún ni gbangba lori ayelujara idakọnkọ ti wọn ṣi pẹlu awọn onibara wọn. Bi wọn ba wa bimọ tan, wọn a bẹrẹ si ni fun omi mu wọn lojoojumọ pẹlu awọn irinṣẹ ti awọn ileeṣẹ nla nla n lo lati fi fun waraa maalu. Lori irọ ni wọn fi gbe maalu Mẹta ti iya n jẹ siwaju ọfiisi wọn nitorii bi ọlọpaa ba fẹ yọju wo nkan to n lọ nibẹ. Ọpọlọpọ ọja ti wọn maa n ko jade latinu ile iṣiṣẹ wọn ni wọn maa n ko lọ oke okun pẹlu fidio ilana ti wọn n gba fun omi ọmu lara wọn ati bi wọn ṣe n sọ ọ di odidi. Ninu ẹrọ kọmputa atawọn iwe ti wọn gba lọwọ wn ni aṣiri ti tu pe lara awọn ololufẹ wọn to maa n wo wọn lo da iléeṣẹ́ fífún omi ọyàn silẹ fun wọn. Awọn oludasilẹ wọn yii lo n san owo fun wọn pẹlu cryptocurrency. Wọn maa n san owo lati ni fidio ti wọn yoo da fi ranṣẹ si eeyan kan ṣoṣo lati wo ati bi wọn ṣe n fun omi ọmu awọn ọmọbinrin. Iroyin sọ pe nigba mii awọn eeeyan kan a diidi bere fun pe ki wọn fun ọmọbinrin kan lara wọn ni irufẹ ounjẹ kan pato jẹ looto ki wọn to fun omi ọmu rẹ bi ẹni to f ra a ṣe fẹ ati pe ninu fidio, ki ọmọbinrin naa sọ pe "omi ọmu yio, tirẹ Mr A tabi Mrs B ni". | https://www.bbc.com/yoruba/56006578 |
1entertainment
| Baba Ijesha: Lẹ́yìn tí a gbọ́ àwíjàre lẹ́nu Dele Matti tó jẹ́ olùdarí eré Ọkọ Iyabọ àti Yomi Fabiyi, a ríi pé wọ́n jẹ̀bi- TAMPAN | Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Yomi Fabiyi ti tun fesi si igbesẹ ẹgbẹ oṣere TAMPAN lori bi wọn ti jawe gbele ẹ fun lori fiimu OKO IYABO to gbe jade. Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita lọjọ Ẹti lo ti kede pe igbesẹ naa waye nitori iwa abuku ati eyi ti ko ba oju mu gẹgẹ bi oṣere ti Fabiyi hu nipa fiimu Ọkọ Iyabọ to gbe jade laipẹ yii. Fiimu naa to gbe jade ni ọjọ Aiku to kọja da lori ọrọ ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan osẹre miran, Baba Ijesha. TAMPAN sọ pe igbesẹ naa waye lẹyin ti oun gbọ awijare Yomi Fabiyi to jẹ olukọtan, olootu ati oludari fiimu naa, ati oludari keji, Ọgbẹni Dele Matti. "A ri pe wọn jẹbi hihu iwa ti ko bojumu fun akọṣẹmọṣẹ oni tiata.'' Amọ, Yomi tutọ soke o tun foju gba a ninu ọrọ to kọ soju opo Instagram rẹ ;ọjọ Abamẹta. Yomi ṣalaye pe oun ko figba kankan jẹ ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, koda oun ko ni kaadi idanimọ ọmọ ẹgbẹ ọhun. TAMPAN kò lè ní kí fíìmù OKO IYABO má jáde, mi kìí ṣ'ọmọ ẹgbẹ́ wọn- Yomi Fabiyi O ni ọpọ awọn gbajugbaja oṣere ni ko ni kaadi idanimọ ẹgbẹ TAMPAN lọwọ ti wọn ṣi n ṣere wọn lọ. ''Ẹgbẹ ANTP ni gbogbo wa jọ wa tẹlẹ, asiko ti to bayii lati pada di ọmọ ẹgbẹ ANTP pada. O dami loju pe inu oloogbe Ogunde yoo dun si eleyii nibi to wa bayii. Ẹ bami bi awọn ọmọ ẹgbẹ TAMPAN pe ki wọn fi fọọmu ti mo fi darapọ mọ ẹgbẹ naa sori ayelujara ki awọn eeyan rii ki wọn si le mọ bo ya ọmọ ẹgbẹ ni mi. Fun idi eyi, iwe lọọ rọkun nle ti wọn kọ si mi, mo ti da a pada fun wọn. Ohun ti gbogbo ẹgbẹ awọn oṣere wa fun ni lati maa ja fawọn ọmọ ẹgbẹ ati lati maa wa igbayegbadun ọmọ ẹgbẹ. Ẹyin TAMPAN, e bi ara yin leere bo ya ẹ n ṣe awọn nkan yii ninu ẹgbẹ. Lẹta ti ẹ kọ si mi, n ko tiẹ ri tiyin ro rara, o si dami loju pe ẹ mọ daju wi pe ko si ẹni to le dami duro lati maa ṣe fiimu ti mo n ṣe mọ. Fiimu to dara ni OKO IYABO, ẹ ko si lagbara lati ṣe ayẹwo rẹ gẹgẹ bi ẹ ṣe sọ ninu lẹta ti ẹ kọ si mi. Ati pe gbogbo awọn awawi yin lori ilana ati ihuwasi ọmọ ẹgbẹ ko ni itumọ kankan. Mo fẹ sọ fun yin pe fiimu naa yoo pada jade laipẹ ti akoko ba ti to. Mo si maa ba awọn agbaagba ẹgbẹ TAMPAN kan sọrọ ki n to gbe igbesẹ to kan,'' Yomi lo ṣalaye bẹẹ. | Baba Ijesha: Lẹ́yìn tí a gbọ́ àwíjàre lẹ́nu Dele Matti tó jẹ́ olùdarí eré Ọkọ Iyabọ àti Yomi Fabiyi, a ríi pé wọ́n jẹ̀bi- TAMPAN Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Yomi Fabiyi ti tun fesi si igbesẹ ẹgbẹ oṣere TAMPAN lori bi wọn ti jawe gbele ẹ fun lori fiimu OKO IYABO to gbe jade. Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita lọjọ Ẹti lo ti kede pe igbesẹ naa waye nitori iwa abuku ati eyi ti ko ba oju mu gẹgẹ bi oṣere ti Fabiyi hu nipa fiimu Ọkọ Iyabọ to gbe jade laipẹ yii. Fiimu naa to gbe jade ni ọjọ Aiku to kọja da lori ọrọ ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan osẹre miran, Baba Ijesha. TAMPAN sọ pe igbesẹ naa waye lẹyin ti oun gbọ awijare Yomi Fabiyi to jẹ olukọtan, olootu ati oludari fiimu naa, ati oludari keji, Ọgbẹni Dele Matti. "A ri pe wọn jẹbi hihu iwa ti ko bojumu fun akọṣẹmọṣẹ oni tiata.'' Amọ, Yomi tutọ soke o tun foju gba a ninu ọrọ to kọ soju opo Instagram rẹ ;ọjọ Abamẹta. Yomi ṣalaye pe oun ko figba kankan jẹ ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, koda oun ko ni kaadi idanimọ ọmọ ẹgbẹ ọhun. TAMPAN kò lè ní kí fíìmù OKO IYABO má jáde, mi kìí ṣ'ọmọ ẹgbẹ́ wọn- Yomi Fabiyi O ni ọpọ awọn gbajugbaja oṣere ni ko ni kaadi idanimọ ẹgbẹ TAMPAN lọwọ ti wọn ṣi n ṣere wọn lọ. ''Ẹgbẹ ANTP ni gbogbo wa jọ wa tẹlẹ, asiko ti to bayii lati pada di ọmọ ẹgbẹ ANTP pada. O dami loju pe inu oloogbe Ogunde yoo dun si eleyii nibi to wa bayii. Ẹ bami bi awọn ọmọ ẹgbẹ TAMPAN pe ki wọn fi fọọmu ti mo fi darapọ mọ ẹgbẹ naa sori ayelujara ki awọn eeyan rii ki wọn si le mọ bo ya ọmọ ẹgbẹ ni mi. Fun idi eyi, iwe lọọ rọkun nle ti wọn kọ si mi, mo ti da a pada fun wọn. Ohun ti gbogbo ẹgbẹ awọn oṣere wa fun ni lati maa ja fawọn ọmọ ẹgbẹ ati lati maa wa igbayegbadun ọmọ ẹgbẹ. Ẹyin TAMPAN, e bi ara yin leere bo ya ẹ n ṣe awọn nkan yii ninu ẹgbẹ. Lẹta ti ẹ kọ si mi, n ko tiẹ ri tiyin ro rara, o si dami loju pe ẹ mọ daju wi pe ko si ẹni to le dami duro lati maa ṣe fiimu ti mo n ṣe mọ. Fiimu to dara ni OKO IYABO, ẹ ko si lagbara lati ṣe ayẹwo rẹ gẹgẹ bi ẹ ṣe sọ ninu lẹta ti ẹ kọ si mi. Ati pe gbogbo awọn awawi yin lori ilana ati ihuwasi ọmọ ẹgbẹ ko ni itumọ kankan. Mo fẹ sọ fun yin pe fiimu naa yoo pada jade laipẹ ti akoko ba ti to. Mo si maa ba awọn agbaagba ẹgbẹ TAMPAN kan sọrọ ki n to gbe igbesẹ to kan,'' Yomi lo ṣalaye bẹẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57790237 |
2health
| Bed Wetting: Tolulope Joseph ní ò lé ní ogún ọdún tí òun fi tọ̀ sílé kí ìwòsàn tó dé | Iwa ki ọmọ maa tọ sile kii se ohun ajeji nilẹ Yoruba eyi to maa n ba obi ati iru ọmọ bẹẹ ninu jẹ lai tete ri ọna abayọ si aisan naa. Ohun to sẹlẹ si Tolulope Joseph ree ẹni to n tọ sile titi di ẹni ọdun marundinlọgbọn. Nigba to n salaye ọpọ idẹyẹsi ati idojuti to dojukọ nitori aisan tọle-tọle, Tolulope ni ọpọ asa abalaye ni oun tẹle lati wa ojutu si aisan naa. O ni oun maa n kunlẹ lati bẹ ọlọ ata ni alẹ, to fi mọ opo ina, ti oun yoo si tun tọ sinu ẹyin ina, ki oun ma baa tọ sile loru. Amọ o ni pabo ni gbogbo awọn igbesẹ naa ja si titi di iwa ti oun ls ka nipa aisan naa lori ayelujara ti wọn n pe ni Enuresisi. Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: Tolulope, to n sinru ilu lọwọ bayii ni ọna abayọ toun ri nipa ohun to n fa aisan tọletọle, ti oun si wa ojutu si, lo mu ki oun kọ iwe jade lati tọ awọn eeyan miran sọna. A ṣe fidio yii pẹlu ifọwọsọpọ pẹlu Oyeyemi Gbenga-Mustapha. | Bed Wetting: Tolulope Joseph ní ò lé ní ogún ọdún tí òun fi tọ̀ sílé kí ìwòsàn tó dé Iwa ki ọmọ maa tọ sile kii se ohun ajeji nilẹ Yoruba eyi to maa n ba obi ati iru ọmọ bẹẹ ninu jẹ lai tete ri ọna abayọ si aisan naa. Ohun to sẹlẹ si Tolulope Joseph ree ẹni to n tọ sile titi di ẹni ọdun marundinlọgbọn. Nigba to n salaye ọpọ idẹyẹsi ati idojuti to dojukọ nitori aisan tọle-tọle, Tolulope ni ọpọ asa abalaye ni oun tẹle lati wa ojutu si aisan naa. O ni oun maa n kunlẹ lati bẹ ọlọ ata ni alẹ, to fi mọ opo ina, ti oun yoo si tun tọ sinu ẹyin ina, ki oun ma baa tọ sile loru. Amọ o ni pabo ni gbogbo awọn igbesẹ naa ja si titi di iwa ti oun ls ka nipa aisan naa lori ayelujara ti wọn n pe ni Enuresisi. Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: Tolulope, to n sinru ilu lọwọ bayii ni ọna abayọ toun ri nipa ohun to n fa aisan tọletọle, ti oun si wa ojutu si, lo mu ki oun kọ iwe jade lati tọ awọn eeyan miran sọna. A ṣe fidio yii pẹlu ifọwọsọpọ pẹlu Oyeyemi Gbenga-Mustapha. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-56453256 |
5sports
| Manchester United vs Manchester City: Ó ti di ìgbà mẹ́ta ní sáà yìí tí Man U dígbájú ru Man City. | Manchester City bẹrẹ idije naa daada, ṣugbọn wọn ko fi bẹ ẹ halẹ lawọn asiko ti bọọlu ba wa ni ikawọ wọn, ṣugbọn Manchester United ni tiẹ gboro pupọ. Agbabọọlu Man U, Anthony Martial lo kọkọ fi goolu sina iya fun Man City nigba ti idije naa wọ iṣẹju mọkandinlọgbọn. Man U tete gba ara wọn silẹ ninu ina ogun ti Man City kọkọ da ni ibẹẹrẹ idije naa, lati igba naa ni wọn si ti n ṣe daada nigba ti idije naa wa laarin iṣẹju mẹẹdogun si ogun isẹju abala akọkọ. Man U fi bọọlu kilọ fun Man City ni ẹẹmelo kan, ki wọn o to fi titete ronu gba bọọlu kan si awọn Man City. Lati igba ti Martial si ti gba bọọlu sinu awọn ni nkan ti n gbona janjan. Botilẹjẹ pe Manchester City ja fita-fita, Manchester United papa tun gba bọọlu miran wọle lati ọwọ Scott McTominay, nigba ti idije naa wọ iṣẹju mẹrindinlọgọrun. Ni aṣọ iyi ba bọ patapata lara Man City, nitori igba kẹta niyii ti Man U na wọn ni saa yii. Idije naa rọrun pupọ ju fun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea. Everton ti faaye gba wọn ju. Abala akọkọ idije naa ko ti i de ibi kan to ti da bi i pe ode ko ni dara fun Carlo Ancelotti. Niṣe ni Chelsea fi ọ̀bẹ̀ goolu ge Everton wẹlẹwẹlẹ. Adilemu fun ẹgbẹ agbabọọlu, Jordan Pickford gọ ara rẹ, ko yara rara bi Mason Mount ọmọ ẹgbẹ agbọọlu Chelsea ṣe ya bara, to si gba bọọlu sinu awọn . Lo ba di ookan soodo nigba ti idije wọ iṣẹju mẹrinla. Ha, adilemu Everton, Jordan Pickford ko tun ri nkankan 'piiki' o. Ṣe ni Pedro rọrọ pẹ 'omi Jordan' silẹ, to si gba bọọlu sinu awọn. Lo ba di meji soodo ni abala akọkọ idije naa. Igba akọkọ ti Pedro yoo gba bọọlu sinu awọn niyẹn ni saa Premier League yii. Nkan i ba tun ṣẹnu're fun Chelsea nigba ti idije naa wọ iṣẹju mejidinlọgbọn. Kini Kurt Zouma n ro naa? O fi bọọlu silẹ fun Richarlison, to gba siwaju, to si paasi rẹ si Dominic Calvert-Lewin, ṣugbọn niṣe ni oun yi bọọlu roborobo lati ọna jijin. Lo ba ja sofo! Ode iya ni Everton lọ pẹlu bi Chelsea ṣe fi iya ajẹbolori ṣe wọn lalejo ni Stamford Bridge. Ko pẹ ti abala keji idije naa bẹrẹ ni William tun fi kun omije oju ẹgbẹ agbabọọlu Everton nigba to gba bọọlu sinu awọn. Lọrọ Everton ba di ajẹkun iya ni o jẹ..., bi orin ẹnikan oke ọhun. Ko pe iṣẹju maarun ti William pa wọn lẹkun, ni Giroud tun bu iyọ si oju egbo adaa'jina wọn, ni Chelsea ba ni ami ayo mẹẹrin, ti odo si dagbada iya bọ Everton l'ọrun. Fẹran jẹkọ gbaa ni idije naa jẹ fun Chelsea. | Manchester United vs Manchester City: Ó ti di ìgbà mẹ́ta ní sáà yìí tí Man U dígbájú ru Man City. Manchester City bẹrẹ idije naa daada, ṣugbọn wọn ko fi bẹ ẹ halẹ lawọn asiko ti bọọlu ba wa ni ikawọ wọn, ṣugbọn Manchester United ni tiẹ gboro pupọ. Agbabọọlu Man U, Anthony Martial lo kọkọ fi goolu sina iya fun Man City nigba ti idije naa wọ iṣẹju mọkandinlọgbọn. Man U tete gba ara wọn silẹ ninu ina ogun ti Man City kọkọ da ni ibẹẹrẹ idije naa, lati igba naa ni wọn si ti n ṣe daada nigba ti idije naa wa laarin iṣẹju mẹẹdogun si ogun isẹju abala akọkọ. Man U fi bọọlu kilọ fun Man City ni ẹẹmelo kan, ki wọn o to fi titete ronu gba bọọlu kan si awọn Man City. Lati igba ti Martial si ti gba bọọlu sinu awọn ni nkan ti n gbona janjan. Botilẹjẹ pe Manchester City ja fita-fita, Manchester United papa tun gba bọọlu miran wọle lati ọwọ Scott McTominay, nigba ti idije naa wọ iṣẹju mẹrindinlọgọrun. Ni aṣọ iyi ba bọ patapata lara Man City, nitori igba kẹta niyii ti Man U na wọn ni saa yii. Idije naa rọrun pupọ ju fun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea. Everton ti faaye gba wọn ju. Abala akọkọ idije naa ko ti i de ibi kan to ti da bi i pe ode ko ni dara fun Carlo Ancelotti. Niṣe ni Chelsea fi ọ̀bẹ̀ goolu ge Everton wẹlẹwẹlẹ. Adilemu fun ẹgbẹ agbabọọlu, Jordan Pickford gọ ara rẹ, ko yara rara bi Mason Mount ọmọ ẹgbẹ agbọọlu Chelsea ṣe ya bara, to si gba bọọlu sinu awọn . Lo ba di ookan soodo nigba ti idije wọ iṣẹju mẹrinla. Ha, adilemu Everton, Jordan Pickford ko tun ri nkankan 'piiki' o. Ṣe ni Pedro rọrọ pẹ 'omi Jordan' silẹ, to si gba bọọlu sinu awọn. Lo ba di meji soodo ni abala akọkọ idije naa. Igba akọkọ ti Pedro yoo gba bọọlu sinu awọn niyẹn ni saa Premier League yii. Nkan i ba tun ṣẹnu're fun Chelsea nigba ti idije naa wọ iṣẹju mejidinlọgbọn. Kini Kurt Zouma n ro naa? O fi bọọlu silẹ fun Richarlison, to gba siwaju, to si paasi rẹ si Dominic Calvert-Lewin, ṣugbọn niṣe ni oun yi bọọlu roborobo lati ọna jijin. Lo ba ja sofo! Ode iya ni Everton lọ pẹlu bi Chelsea ṣe fi iya ajẹbolori ṣe wọn lalejo ni Stamford Bridge. Ko pẹ ti abala keji idije naa bẹrẹ ni William tun fi kun omije oju ẹgbẹ agbabọọlu Everton nigba to gba bọọlu sinu awọn. Lọrọ Everton ba di ajẹkun iya ni o jẹ..., bi orin ẹnikan oke ọhun. Ko pe iṣẹju maarun ti William pa wọn lẹkun, ni Giroud tun bu iyọ si oju egbo adaa'jina wọn, ni Chelsea ba ni ami ayo mẹẹrin, ti odo si dagbada iya bọ Everton l'ọrun. Fẹran jẹkọ gbaa ni idije naa jẹ fun Chelsea. | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-51793361 |
4religion
| Eid el Kabir: Àwọn ohun mẹ́sàn án tí Mùsùlùmí gbọdọ̀ ṣe nínú oṣù Dhual rèé | Anabi Muhammad (SAW) sọ pe ko si ọjọ kankan to ṣe koko julọ ninu ọdun kan ju ọjọ mẹwaa akọkọ ninu oṣu Dhu al- Hijjah. Awọn onimọ ti rọ awọn Musulumi lati mu ọjọ mẹwaa akọkọ oṣu Dhul Hijjah lẹyin ti wọn ti kede ọjọru gẹgẹ bi ọjọ kinni, oṣu kejila kalẹnda musulumi. Awọn Musulumi maa ri ọjọ mẹwaa akọkọ oṣu Dhul al- Hijjah gẹgẹ bi eyi to se pataki julọ niwaju Ọlọrun. Bakan naa ni wọn ni gbogbo adura ati aawẹ ti Musulumi ba se ni ọjọ naa yoo goke arafa lọ ni ibi ti o sunmọ Ọlọrun julọ Sheikh Aminu Ibrahim Dauraea to jẹ ilumọọka onimọ ẹsin Islam ni orile-ede yii salaye fun BBC nipa gbogbo awọn nkan to rọ mọ Oṣu Dhu al- Hijjah ati awọn nkan ti musulumi gbọdọ ṣe. Ma ṣe ge irun tabi fa eekanna rẹ Nkan akọkọ ni pe ti enikan ba n gbiyanju lati se aluwala, lati ọjọ akọkọ, oṣu Dhu al - Hijjah, ma se ge eekanna rẹ tabi ki o fa irun kankan lara. Nitori pe Allah (SAWA) yoo se alekun ati ibukun si irun kọọkan ati bi eekanna naa ba ṣe gun to, titi di asiko ti yoo fi ge irun rẹ tabi eekanna. Gba aawẹ lọjọ Arafa Gẹgẹ bi Sheikh Daurawa sr sọ, nkan ikeji ni lati gba aawẹ lọjọ Arafa. Hadiiti sọ pe aawẹ lọjọ Arafa maa n pa gbogbo ẹsẹ ọdun to kọja ati eyi to n bọ rẹ Irubọ/Itọrẹ Nkan kẹta, o ṣe pataki lati ṣe itọrẹ aanu, eyi tọ sunnah Anabi Ibrahim (SAWA) ti Allah pa laṣẹ gẹgẹ bi adanwo lati fi ọmọ rẹ rubọ, o setan lati ṣe ki Ọlọrun to fi Agbo rọpo ọmọ rẹ. Lọ si Yidi O ṣe pataki bakan naa ki eniyan lọ fun adua yidi lọjọ ọdun ileya, ki eniyan si wọ asọ tuntun. Ti oo ba wa ni aṣọ tuntun; o ṣe pataki lati wọ eyi to dara ju ninu awọn aṣọ ti o ni. O gbọdọ dara si awọn ẹbi rẹ ki o si ra aṣọ tuntun fun wọn ti o ba lagbara rẹ, ki wọn si lọ yidi pẹlu awọn obinrin. Oṣu aawẹ ni Dhu al- Hijjah Yatọ si pe o gba aawẹ lọjọ Arafa, o ṣe pataki lati gbawẹ lati ibere lẹẹkan oṣu naa. Fikun iṣẹ oore ṣiṣe O ṣe pataki lati maa ṣe saara nigbagbogbo ni oṣu Dhu al-Hijjah Bi apẹrẹ, ti o ba n sẹ ọrẹ ẹgbẹrun kan Naira, o ni lati fi kun un tabi ki o ṣe ni ilopo Nkan miran tun ni pe ẹni ti ko ba lọsi Hajj ọdun yii, o yẹ ko fi ilaji owo rẹ ra ounjẹ ati aṣọ fun awọn alaini, iṣẹ oore naa ni. Ṣe abẹwo si awọn ọrẹ ati ẹbi rẹ Nkan to yẹ Musulumi ni lati maa ṣe abẹwo si ẹbi ati ọrẹ ninu oṣu yii Kikọ itẹ oku O ṣe pataki lati ṣe afikun iye awon itẹ oku ni asiko oṣu ibukun yii. O se pataki lati kọ awon saare oku ti wọn o kọ akọle bii Allahu Akbar, Allahu Akbar, La'ilaha illalLah Allahu Akbar, Allahu Akbar walillahil hamdu sii Lilọ Hajj O ṣe pataki lati lọ Hajj tabi Umurah. Onimọ naa sọ pe awọn iṣesi yii lo ti ṣe akotan gbogbo opo ẹsin musulumi. Idi niyi ti won ṣe rọ musulumi lati tiraka lati ṣe gbogno nkan wọnyi ninu oṣu mimọ yii. Oriṣiriṣi eto amuludun, to fi mọ ẹṣin gigun lo ma n waye lasiko ọdun Ileya nilẹ Hausa. Arun coronavirus si ni ijọba sọ pe o mu ki wọn o fagile adura Eid l'ọdun yii, lati ri i pe ero ko pọju ki aarun naa ma ba a tun ran si. Iyalẹnu ni adura Eid ti ko ni i waye jẹ fun awọn kan nilu Kano, nitori pe ko si isede mọ, ati pe ọdun ileya akọkọ niyii ti Emir ilu Kano, Alhaji Aminu Ado Bayero, yoo ṣe lori itẹ. Kii ṣe ilu Kano nikan ni yoo ṣafẹẹri ọdun adura Eid, ọrọ yii kan awọn ilu nla bi i Rano, Gaya, Karaye, ati Bichi to wa ni ipinlẹ Kano. Ṣugbọn ṣa, eyi kọ ni igba akọkọ ti wọn fi ofin de adura agbapọ, nitori awọn idi l'oriṣiriṣi. Laarin ọdun 1981 si 1983, ayẹyẹ Hawan Sallah ko waye, nitori aawọ to wa laarin gomina igba naa, Abubakar Rimi, ati Emir to wa lori oye. Ayẹyẹ Hawan Sallah jẹ eto pataki, ninu eyi ti Emir ti ma n gun ẹṣin yipo ilu Kano, ti awọn eeyan yoo si ma a kan saara si. Bakan naa lọdun 2012, Igbimọ lọbalọba ilu Kano, fi ofin de adura Eid, nitori pe ara Emir ilu Kano nigba naa, Alhaji Ado Bayero ko ya. Eyi ko ṣẹlẹ ri lati bi igba ọdun ti adura Eid ti n waye nilu Kano. Amọ ero awọn kan yatọ lori eyi, igbagbọ wọn ni pe irẹpọ ti ko si laarin igbimọ lọbalọba ati ijọba ipinlẹ Kano, lo fa igbesẹ naa. Eto adura ko tun waye lọdun 2013. Ayẹyẹ kankan ko si waye titi di ọdun 2014, lẹyin iku Emir Ado Bayero. Ọdun 2019 ni ijọba ipinlẹ Kano,tun fi ofin de eto adura, eyi to ba awọn ọdọ ati awọn ọmọbinrin lọkan jẹ pupọ. Bo tilẹ jẹ pe eto aabo nijọba sọ pe o fa igbesẹ naa, o foju han pe nitori ija to wa laarin igbimọ lọbalọba ati ijọba lo fa a. Eto adura ko tun waye lasiko itunu awẹ ọdun 2020, nitori itankalẹ coronavirus. Bakan naa ni ọmọ ṣori ni ipinlẹ Ogun lọdun yii: Kò ní sí ayẹyẹ ọdún Ojúde Oba lọ́dún yìí- Awujale ilẹ̀ Ijebu Ọba Sikiru Adetona ti ilẹ̀ Ijebu ti kéde pé ayẹyẹ ọdún Ojude Oba kò ní wáyé lọ́dún yìí. Ojude Oba festival: Kò ní sí ayẹyẹ Ojúde Oba lọ́dún yìí nítorí Coronavirus- Ọba Sikiru Adetona Awujale ati alaṣẹ agba ilẹ Ijebu, Ọba Sikiru Adetona ti kede pe ayẹyẹ ọdun Ojude Oba tọdun 2020 ko ni waye nitori arun Covid-19. Ajakalẹ arun coronavirus yii lo n gba ẹbọ lọwọ gbogbo agbaye lati oṣu kejila, ọdun 2019 to ti bẹrẹ ni China. Ohun naa lo si ti mu ayipada ba eto ẹkọ, irin ajo afẹ ati awọn nkan ọlọdọọọdun miran kaakiri agbaye Oba Adetona lo kede pe Covid 19 yii ko ni jẹ ki ọdun yii waye ninu atẹjade kan ti Ebumawe ti Ago-Iwoye, Oba A.A. Adenugba fọwọ si. O ni o ṣe pataki ki ayẹyẹ ọdun ọhun ma waye nitori ajakalẹ arun Coronavirus to n ba gbogbo agbaye finra, ti ko si yọ Naijiria sẹyin. Oba ọhun rọ awọn ara ilu lati tẹle gbogbo ilana ti ajọ NCDC gbe kalẹ bii ọwọ fifọ loorekoore ati ijinasiraẹni lawujọ lọna ati le arun naa lọ. Lẹyin naa lo parọwa si awọn ọmọ bibi ilẹ Ijebu lati ṣe ọdun ọhun laaye ara wọn lai si ariwo. Ti ẹ ko ba gbagbe, ọdun Ojude Oba maa n waye lọdọọdun ni ọjọ kẹta ọdun Ileya ti awọn Musulumi maa n ṣe. Ṣaaju ni Ijọba Kano na ti paṣẹ pe: Ijọba Kano wọgile ayẹyẹ to maa n waye lẹyin irun ọdun Ileya: Ko tan sibẹ o, ijọba ipinlẹ naa tun ti wọgile ayẹyẹ ọdun ileya ọdun 2020 nitori Covid-19. Lojuna ati fopin si itankalẹ aarun Coronavirus ni ipinlẹ Kano, ijọba ti kede lọjọru pe oun wọgile gbogbo ayẹyẹ ọdun Eid-el-Kabir. Apejọpọ Hawan Daushe ti Emir maa n bẹ gomina wo nile ìjọba l'agbegbe Shettima House laarin awọn ayẹyẹ to ku ko ni waye. Kọmísọ́nnà fun ọrọ to n lọ ni Kano, Muhammed Garba, sọ pe eyi jẹ ọkan lara igbese ijọba lati tubọ tesiwaju ninu aseyọri rẹ lati gbogun ti aarun Covid-19. Eid-el-Kabir jẹ ayẹyẹ to mọ julọ ti awon misulumi maa n se lati buyi kun ifẹ Ibrahim to gba lati fi ọmọ rẹ rubọ, ni igbọran si aṣẹ Ọlọrun Garba ni ipinnu ijọba yii ko sẹyii ifẹnuko igbimọ alaṣẹ leyin ipade to waye. O ni àwọn igbimọ fẹnuko pe ki awon eniyan kirun janmọ jakejado ipinlẹ Kano, sugbọn ki wọn tẹle ilana ijina sira ẹni ati gbogbo ilana lati dẹkun aarun Covid19 ni agbegbe ibi irun janmọ Garba kede pe ijọba yoo pese gbogbo awon nkan aabo ti won yoo nilo, bii iboju ati 'hand sanitizer' ti won yoo lo. O ni: "Gbogbo Emir Kano Maraarun ni yoo lọ yidi ni agbegbe wọn ninu mọtọ." "Awọn alaṣẹ ijọba kọọkan ni yoo samoju to eto yidi ni agbegbe wọn lati rii daju pe awọn olujọsin tẹle ilana ijọba lori Covid-19 "Alaye Garba ree" Bí Coronavirus ṣé jẹ́ kí Awujalẹ wọ́gilé Ojúde Ọba ní Ijẹbu-Ode, bẹ́ẹ̀ náà ló tún ti jẹ́ kí Ganduje wọ́gilé ayẹyẹ 'Hawan Daushe' to máa n waye ninu ọdun Ileya ni Kano. | Eid el Kabir: Àwọn ohun mẹ́sàn án tí Mùsùlùmí gbọdọ̀ ṣe nínú oṣù Dhual rèé Anabi Muhammad (SAW) sọ pe ko si ọjọ kankan to ṣe koko julọ ninu ọdun kan ju ọjọ mẹwaa akọkọ ninu oṣu Dhu al- Hijjah. Awọn onimọ ti rọ awọn Musulumi lati mu ọjọ mẹwaa akọkọ oṣu Dhul Hijjah lẹyin ti wọn ti kede ọjọru gẹgẹ bi ọjọ kinni, oṣu kejila kalẹnda musulumi. Awọn Musulumi maa ri ọjọ mẹwaa akọkọ oṣu Dhul al- Hijjah gẹgẹ bi eyi to se pataki julọ niwaju Ọlọrun. Bakan naa ni wọn ni gbogbo adura ati aawẹ ti Musulumi ba se ni ọjọ naa yoo goke arafa lọ ni ibi ti o sunmọ Ọlọrun julọ Sheikh Aminu Ibrahim Dauraea to jẹ ilumọọka onimọ ẹsin Islam ni orile-ede yii salaye fun BBC nipa gbogbo awọn nkan to rọ mọ Oṣu Dhu al- Hijjah ati awọn nkan ti musulumi gbọdọ ṣe. Ma ṣe ge irun tabi fa eekanna rẹ Nkan akọkọ ni pe ti enikan ba n gbiyanju lati se aluwala, lati ọjọ akọkọ, oṣu Dhu al - Hijjah, ma se ge eekanna rẹ tabi ki o fa irun kankan lara. Nitori pe Allah (SAWA) yoo se alekun ati ibukun si irun kọọkan ati bi eekanna naa ba ṣe gun to, titi di asiko ti yoo fi ge irun rẹ tabi eekanna. Gba aawẹ lọjọ Arafa Gẹgẹ bi Sheikh Daurawa sr sọ, nkan ikeji ni lati gba aawẹ lọjọ Arafa. Hadiiti sọ pe aawẹ lọjọ Arafa maa n pa gbogbo ẹsẹ ọdun to kọja ati eyi to n bọ rẹ Irubọ/Itọrẹ Nkan kẹta, o ṣe pataki lati ṣe itọrẹ aanu, eyi tọ sunnah Anabi Ibrahim (SAWA) ti Allah pa laṣẹ gẹgẹ bi adanwo lati fi ọmọ rẹ rubọ, o setan lati ṣe ki Ọlọrun to fi Agbo rọpo ọmọ rẹ. Lọ si Yidi O ṣe pataki bakan naa ki eniyan lọ fun adua yidi lọjọ ọdun ileya, ki eniyan si wọ asọ tuntun. Ti oo ba wa ni aṣọ tuntun; o ṣe pataki lati wọ eyi to dara ju ninu awọn aṣọ ti o ni. O gbọdọ dara si awọn ẹbi rẹ ki o si ra aṣọ tuntun fun wọn ti o ba lagbara rẹ, ki wọn si lọ yidi pẹlu awọn obinrin. Oṣu aawẹ ni Dhu al- Hijjah Yatọ si pe o gba aawẹ lọjọ Arafa, o ṣe pataki lati gbawẹ lati ibere lẹẹkan oṣu naa. Fikun iṣẹ oore ṣiṣe O ṣe pataki lati maa ṣe saara nigbagbogbo ni oṣu Dhu al-Hijjah Bi apẹrẹ, ti o ba n sẹ ọrẹ ẹgbẹrun kan Naira, o ni lati fi kun un tabi ki o ṣe ni ilopo Nkan miran tun ni pe ẹni ti ko ba lọsi Hajj ọdun yii, o yẹ ko fi ilaji owo rẹ ra ounjẹ ati aṣọ fun awọn alaini, iṣẹ oore naa ni. Ṣe abẹwo si awọn ọrẹ ati ẹbi rẹ Nkan to yẹ Musulumi ni lati maa ṣe abẹwo si ẹbi ati ọrẹ ninu oṣu yii Kikọ itẹ oku O ṣe pataki lati ṣe afikun iye awon itẹ oku ni asiko oṣu ibukun yii. O se pataki lati kọ awon saare oku ti wọn o kọ akọle bii Allahu Akbar, Allahu Akbar, La'ilaha illalLah Allahu Akbar, Allahu Akbar walillahil hamdu sii Lilọ Hajj O ṣe pataki lati lọ Hajj tabi Umurah. Onimọ naa sọ pe awọn iṣesi yii lo ti ṣe akotan gbogbo opo ẹsin musulumi. Idi niyi ti won ṣe rọ musulumi lati tiraka lati ṣe gbogno nkan wọnyi ninu oṣu mimọ yii. Oriṣiriṣi eto amuludun, to fi mọ ẹṣin gigun lo ma n waye lasiko ọdun Ileya nilẹ Hausa. Arun coronavirus si ni ijọba sọ pe o mu ki wọn o fagile adura Eid l'ọdun yii, lati ri i pe ero ko pọju ki aarun naa ma ba a tun ran si. Iyalẹnu ni adura Eid ti ko ni i waye jẹ fun awọn kan nilu Kano, nitori pe ko si isede mọ, ati pe ọdun ileya akọkọ niyii ti Emir ilu Kano, Alhaji Aminu Ado Bayero, yoo ṣe lori itẹ. Kii ṣe ilu Kano nikan ni yoo ṣafẹẹri ọdun adura Eid, ọrọ yii kan awọn ilu nla bi i Rano, Gaya, Karaye, ati Bichi to wa ni ipinlẹ Kano. Ṣugbọn ṣa, eyi kọ ni igba akọkọ ti wọn fi ofin de adura agbapọ, nitori awọn idi l'oriṣiriṣi. Laarin ọdun 1981 si 1983, ayẹyẹ Hawan Sallah ko waye, nitori aawọ to wa laarin gomina igba naa, Abubakar Rimi, ati Emir to wa lori oye. Ayẹyẹ Hawan Sallah jẹ eto pataki, ninu eyi ti Emir ti ma n gun ẹṣin yipo ilu Kano, ti awọn eeyan yoo si ma a kan saara si. Bakan naa lọdun 2012, Igbimọ lọbalọba ilu Kano, fi ofin de adura Eid, nitori pe ara Emir ilu Kano nigba naa, Alhaji Ado Bayero ko ya. Eyi ko ṣẹlẹ ri lati bi igba ọdun ti adura Eid ti n waye nilu Kano. Amọ ero awọn kan yatọ lori eyi, igbagbọ wọn ni pe irẹpọ ti ko si laarin igbimọ lọbalọba ati ijọba ipinlẹ Kano, lo fa igbesẹ naa. Eto adura ko tun waye lọdun 2013. Ayẹyẹ kankan ko si waye titi di ọdun 2014, lẹyin iku Emir Ado Bayero. Ọdun 2019 ni ijọba ipinlẹ Kano,tun fi ofin de eto adura, eyi to ba awọn ọdọ ati awọn ọmọbinrin lọkan jẹ pupọ. Bo tilẹ jẹ pe eto aabo nijọba sọ pe o fa igbesẹ naa, o foju han pe nitori ija to wa laarin igbimọ lọbalọba ati ijọba lo fa a. Eto adura ko tun waye lasiko itunu awẹ ọdun 2020, nitori itankalẹ coronavirus. Bakan naa ni ọmọ ṣori ni ipinlẹ Ogun lọdun yii: Kò ní sí ayẹyẹ ọdún Ojúde Oba lọ́dún yìí- Awujale ilẹ̀ Ijebu Ọba Sikiru Adetona ti ilẹ̀ Ijebu ti kéde pé ayẹyẹ ọdún Ojude Oba kò ní wáyé lọ́dún yìí. Ojude Oba festival: Kò ní sí ayẹyẹ Ojúde Oba lọ́dún yìí nítorí Coronavirus- Ọba Sikiru Adetona Awujale ati alaṣẹ agba ilẹ Ijebu, Ọba Sikiru Adetona ti kede pe ayẹyẹ ọdun Ojude Oba tọdun 2020 ko ni waye nitori arun Covid-19. Ajakalẹ arun coronavirus yii lo n gba ẹbọ lọwọ gbogbo agbaye lati oṣu kejila, ọdun 2019 to ti bẹrẹ ni China. Ohun naa lo si ti mu ayipada ba eto ẹkọ, irin ajo afẹ ati awọn nkan ọlọdọọọdun miran kaakiri agbaye Oba Adetona lo kede pe Covid 19 yii ko ni jẹ ki ọdun yii waye ninu atẹjade kan ti Ebumawe ti Ago-Iwoye, Oba A.A. Adenugba fọwọ si. O ni o ṣe pataki ki ayẹyẹ ọdun ọhun ma waye nitori ajakalẹ arun Coronavirus to n ba gbogbo agbaye finra, ti ko si yọ Naijiria sẹyin. Oba ọhun rọ awọn ara ilu lati tẹle gbogbo ilana ti ajọ NCDC gbe kalẹ bii ọwọ fifọ loorekoore ati ijinasiraẹni lawujọ lọna ati le arun naa lọ. Lẹyin naa lo parọwa si awọn ọmọ bibi ilẹ Ijebu lati ṣe ọdun ọhun laaye ara wọn lai si ariwo. Ti ẹ ko ba gbagbe, ọdun Ojude Oba maa n waye lọdọọdun ni ọjọ kẹta ọdun Ileya ti awọn Musulumi maa n ṣe. Ṣaaju ni Ijọba Kano na ti paṣẹ pe: Ijọba Kano wọgile ayẹyẹ to maa n waye lẹyin irun ọdun Ileya: Ko tan sibẹ o, ijọba ipinlẹ naa tun ti wọgile ayẹyẹ ọdun ileya ọdun 2020 nitori Covid-19. Lojuna ati fopin si itankalẹ aarun Coronavirus ni ipinlẹ Kano, ijọba ti kede lọjọru pe oun wọgile gbogbo ayẹyẹ ọdun Eid-el-Kabir. Apejọpọ Hawan Daushe ti Emir maa n bẹ gomina wo nile ìjọba l'agbegbe Shettima House laarin awọn ayẹyẹ to ku ko ni waye. Kọmísọ́nnà fun ọrọ to n lọ ni Kano, Muhammed Garba, sọ pe eyi jẹ ọkan lara igbese ijọba lati tubọ tesiwaju ninu aseyọri rẹ lati gbogun ti aarun Covid-19. Eid-el-Kabir jẹ ayẹyẹ to mọ julọ ti awon misulumi maa n se lati buyi kun ifẹ Ibrahim to gba lati fi ọmọ rẹ rubọ, ni igbọran si aṣẹ Ọlọrun Garba ni ipinnu ijọba yii ko sẹyii ifẹnuko igbimọ alaṣẹ leyin ipade to waye. O ni àwọn igbimọ fẹnuko pe ki awon eniyan kirun janmọ jakejado ipinlẹ Kano, sugbọn ki wọn tẹle ilana ijina sira ẹni ati gbogbo ilana lati dẹkun aarun Covid19 ni agbegbe ibi irun janmọ Garba kede pe ijọba yoo pese gbogbo awon nkan aabo ti won yoo nilo, bii iboju ati 'hand sanitizer' ti won yoo lo. O ni: "Gbogbo Emir Kano Maraarun ni yoo lọ yidi ni agbegbe wọn ninu mọtọ." "Awọn alaṣẹ ijọba kọọkan ni yoo samoju to eto yidi ni agbegbe wọn lati rii daju pe awọn olujọsin tẹle ilana ijọba lori Covid-19 "Alaye Garba ree" Bí Coronavirus ṣé jẹ́ kí Awujalẹ wọ́gilé Ojúde Ọba ní Ijẹbu-Ode, bẹ́ẹ̀ náà ló tún ti jẹ́ kí Ganduje wọ́gilé ayẹyẹ 'Hawan Daushe' to máa n waye ninu ọdun Ileya ni Kano. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-53324410 |
3politics
| O ti fihàn pé lóòtọ́ ni o kò sí fún ẹnikẹ́ni, Tinubu kọ̀wé ráńṣẹ́ sí Ààrẹ Buhari | Olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti kan sáárá sí Ààrẹ Muhammadu Buhari fún ipa ribiribi tó kó níbi ètò abẹ́nú ẹgbẹ́ náà. Tinubu ní ṣaájú kí ètò ìdìbò abẹ́nú náà tó wáyé ní ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 ni àwọn ti ń bẹ Ààrẹ Buhari láti kéde ẹnìkan gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò jẹ Ààrẹ lẹ́yìn ṣùgbọ́n Ààrẹ kọ̀ jálẹ̀. Nínú ìwé àkọráńṣẹ́ kan tí Tinubu kọ sí Ààrẹ Buhari èyí tí olùbádàmọ̀ràn pàtàkì sí Ààrẹ lórí ìròyìn àti ìpolongo, Femi Adesina fi léde ni Tinubu ní ó hàn gbangba pé Ààrẹ Buhari kò sí fún ẹnìkan ní tòótọ́. Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ni àwọn ti ń retí kí Ààrẹ kéde pé ẹnìkan tí òun fọwọ́ sí gẹ́gẹ́ bí olùdíje, ṣùgbọ́n Ààrẹ kọ̀ láti yan ẹnìkan sójú tó sì fún gbogbo àwọn láyè láti díje. Ó ní ó jẹ́ ohun ìwúrí fún òun tí inú òun sì dùn pé Ààrẹ dúró dáńfó gedegbe láàárín gbogbo àwọn olùdíje pàápàá nígbà tí oníkálùkù bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ohun tí wọ́n ní lọ́kàn láti ṣe fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Tinubu fi kun pé lásìkò ìbò gan ní òun ṣàwárí rẹ̀ pé gbogbo àwọn olùdíje ni Ààrẹ Buhari ń fẹ́, ní èyí tó ní ó hàn nínú akọráńṣẹ́ tí Ààrẹ Buhari kọ́kọ́ kọ sí òun láti fi kí òun kú oríire ìjáwé olúborí. Ó tẹ̀síwájú pé inú òun dún pé gbogbo àwọn ènìyàn ẹgbẹ́ àwọn yan òun gẹ́gẹ́ bí olùdíje wọn, àmọ́ ó ní èyí kò ní ṣeéṣe tí Ààrẹ Buhari kò bá fọwọ́ si. Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC fún ipa takuntakun tí wọ́n kó lásìkò ètò abẹ́nú náà. Ó ní gbogbo àwọn ìpèníjá tó ń bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fínra ni òun yóò ri dájú pé òun fi sínú ètò ìpolongo àti pé ohun ni àwọn yóò kojú. Bẹ́ẹ̀ náà ló ní òun ti ń kàn sí àwọn tí àwọn jọ díje ní ọ̀kọ̀ọ̀kan lójúnà láti mú ìṣọ̀kan àti ìlọsíwájú bá ẹgbẹ́. | O ti fihàn pé lóòtọ́ ni o kò sí fún ẹnikẹ́ni, Tinubu kọ̀wé ráńṣẹ́ sí Ààrẹ Buhari Olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti kan sáárá sí Ààrẹ Muhammadu Buhari fún ipa ribiribi tó kó níbi ètò abẹ́nú ẹgbẹ́ náà. Tinubu ní ṣaájú kí ètò ìdìbò abẹ́nú náà tó wáyé ní ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 ni àwọn ti ń bẹ Ààrẹ Buhari láti kéde ẹnìkan gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò jẹ Ààrẹ lẹ́yìn ṣùgbọ́n Ààrẹ kọ̀ jálẹ̀. Nínú ìwé àkọráńṣẹ́ kan tí Tinubu kọ sí Ààrẹ Buhari èyí tí olùbádàmọ̀ràn pàtàkì sí Ààrẹ lórí ìròyìn àti ìpolongo, Femi Adesina fi léde ni Tinubu ní ó hàn gbangba pé Ààrẹ Buhari kò sí fún ẹnìkan ní tòótọ́. Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ni àwọn ti ń retí kí Ààrẹ kéde pé ẹnìkan tí òun fọwọ́ sí gẹ́gẹ́ bí olùdíje, ṣùgbọ́n Ààrẹ kọ̀ láti yan ẹnìkan sójú tó sì fún gbogbo àwọn láyè láti díje. Ó ní ó jẹ́ ohun ìwúrí fún òun tí inú òun sì dùn pé Ààrẹ dúró dáńfó gedegbe láàárín gbogbo àwọn olùdíje pàápàá nígbà tí oníkálùkù bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ohun tí wọ́n ní lọ́kàn láti ṣe fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Tinubu fi kun pé lásìkò ìbò gan ní òun ṣàwárí rẹ̀ pé gbogbo àwọn olùdíje ni Ààrẹ Buhari ń fẹ́, ní èyí tó ní ó hàn nínú akọráńṣẹ́ tí Ààrẹ Buhari kọ́kọ́ kọ sí òun láti fi kí òun kú oríire ìjáwé olúborí. Ó tẹ̀síwájú pé inú òun dún pé gbogbo àwọn ènìyàn ẹgbẹ́ àwọn yan òun gẹ́gẹ́ bí olùdíje wọn, àmọ́ ó ní èyí kò ní ṣeéṣe tí Ààrẹ Buhari kò bá fọwọ́ si. Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC fún ipa takuntakun tí wọ́n kó lásìkò ètò abẹ́nú náà. Ó ní gbogbo àwọn ìpèníjá tó ń bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fínra ni òun yóò ri dájú pé òun fi sínú ètò ìpolongo àti pé ohun ni àwọn yóò kojú. Bẹ́ẹ̀ náà ló ní òun ti ń kàn sí àwọn tí àwọn jọ díje ní ọ̀kọ̀ọ̀kan lójúnà láti mú ìṣọ̀kan àti ìlọsíwájú bá ẹgbẹ́. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/c9wkywd7dj2o |
4religion
| Religion tolerance in Nigeria: Obìnrin Mùsùlùmí ní òun ṣe ilé àlùfà ní ọ̀ṣọ́ kérésì láti polongo ìrẹ́pọ̀ | Ramatu Tijjani, ẹlẹsin Musulumi kan to n gbe ni ipinlẹ Kaduna, ti ṣe ile alufa kan, Mobel Wuye lọṣọ pẹlu 'igi Keresi'. Tijjani, to jẹ aṣoju ajọ alaafia sọ pe, Keresimesi ma n fun awọn Musulumi ni anfaani lati fihan awọn aladugbo wọn to jẹ Kristiẹni pe, ẹsin alaafia, ifẹ ati ipamọra ni Islam. O ṣalaye pe oun gbe igbesẹ naa lati polongo alaafia ati irẹpọ, ati lati mu ki alaafia jọba laarin awọn ẹlẹsin mejeeji. "Keresimesi ma n fun awọn Musulumi ni anfaani lati ro ibaṣepọ wọn pẹlu aladugbo to jẹ Kristiẹni. Idi si niyii ti mo fi ma n ya owo sọtọ lati fi ra ounjẹ ati awọn nkan mii, lati pin fun awọn ọrẹ ati ẹbi mi." Tijjani sọ pe oun ṣe ile alufa naa ni ọṣọ, lati bu ẹwa kun pẹlu igi, ina, aṣọ ati awọn nkan ẹṣọ mii. O ni "mo ṣakiyesi pe igi Keresimesi ṣe pataki si gbogbo Kristiẹni kaakiri agbaye, lo jẹ ki n ṣe bẹ ẹ fun alufa, ati lati ki gbogbo Kristiẹni ku ọdun ati imurasilẹ fun ọdun tuntun". O ṣalaye pe lati bi ọdun mẹwaa ni oun ti n pin igi Keresimesi fun adari ẹsin Kristiẹni, pẹlu iwoye pe ọrọ ẹsin ati oṣelu ti ba ọpọlọpọ nkan jẹ ni Naijiria, to si tun n mu ifasẹyin ba alaafia. Alufa Wuye to fi ẹmi imoore han sọ pe, idunnu ati iyalẹnu ni ẹbun Tijjani jẹ fun oun, nitori pe oun ko gba iru ẹbun bẹ ẹ ri lọwọ obinrin Musulumi. Bakan naa ni iroyin mii sọ pe obinrin musulumi miran, Hajia Ramatu tun fi igi Keresi se ọsọ ni ile alaga ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi CAN to wa nilu Kaduna, Ẹni-ọwọ Hayap. Ramatu ni oun naa lo anfaani akoko keresi yii lati tan ọrọ ifẹ, alaafia, irẹpọ ati ipamọra kalẹ ni. Nigba to n fi ẹmi imoore rẹ han si Hajia Ramatu, Ẹni-ọwọ Hayap mọriri ọwọ ọrẹ naa, to si se apejuwe obinrin musulumi ọhun bii ẹlẹyinju aanu. | Religion tolerance in Nigeria: Obìnrin Mùsùlùmí ní òun ṣe ilé àlùfà ní ọ̀ṣọ́ kérésì láti polongo ìrẹ́pọ̀ Ramatu Tijjani, ẹlẹsin Musulumi kan to n gbe ni ipinlẹ Kaduna, ti ṣe ile alufa kan, Mobel Wuye lọṣọ pẹlu 'igi Keresi'. Tijjani, to jẹ aṣoju ajọ alaafia sọ pe, Keresimesi ma n fun awọn Musulumi ni anfaani lati fihan awọn aladugbo wọn to jẹ Kristiẹni pe, ẹsin alaafia, ifẹ ati ipamọra ni Islam. O ṣalaye pe oun gbe igbesẹ naa lati polongo alaafia ati irẹpọ, ati lati mu ki alaafia jọba laarin awọn ẹlẹsin mejeeji. "Keresimesi ma n fun awọn Musulumi ni anfaani lati ro ibaṣepọ wọn pẹlu aladugbo to jẹ Kristiẹni. Idi si niyii ti mo fi ma n ya owo sọtọ lati fi ra ounjẹ ati awọn nkan mii, lati pin fun awọn ọrẹ ati ẹbi mi." Tijjani sọ pe oun ṣe ile alufa naa ni ọṣọ, lati bu ẹwa kun pẹlu igi, ina, aṣọ ati awọn nkan ẹṣọ mii. O ni "mo ṣakiyesi pe igi Keresimesi ṣe pataki si gbogbo Kristiẹni kaakiri agbaye, lo jẹ ki n ṣe bẹ ẹ fun alufa, ati lati ki gbogbo Kristiẹni ku ọdun ati imurasilẹ fun ọdun tuntun". O ṣalaye pe lati bi ọdun mẹwaa ni oun ti n pin igi Keresimesi fun adari ẹsin Kristiẹni, pẹlu iwoye pe ọrọ ẹsin ati oṣelu ti ba ọpọlọpọ nkan jẹ ni Naijiria, to si tun n mu ifasẹyin ba alaafia. Alufa Wuye to fi ẹmi imoore han sọ pe, idunnu ati iyalẹnu ni ẹbun Tijjani jẹ fun oun, nitori pe oun ko gba iru ẹbun bẹ ẹ ri lọwọ obinrin Musulumi. Bakan naa ni iroyin mii sọ pe obinrin musulumi miran, Hajia Ramatu tun fi igi Keresi se ọsọ ni ile alaga ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi CAN to wa nilu Kaduna, Ẹni-ọwọ Hayap. Ramatu ni oun naa lo anfaani akoko keresi yii lati tan ọrọ ifẹ, alaafia, irẹpọ ati ipamọra kalẹ ni. Nigba to n fi ẹmi imoore rẹ han si Hajia Ramatu, Ẹni-ọwọ Hayap mọriri ọwọ ọrẹ naa, to si se apejuwe obinrin musulumi ọhun bii ẹlẹyinju aanu. | https://www.bbc.com/yoruba/awon-iroyin-miran-55360247 |
2health
| Uses of Garlic: Mọ̀ síi nípa àǹfàní tí lílo Aáyù lè fún ìlera ìwọ àti ẹbí rẹ | Ilumọọka nkan isebẹ ti o loorun aladun ni Garlic tabi aayu jẹ. O kun fun eronja taa n pe ni Sulphur eyi to mu ki o maa se ara loore pupọ Orisirisi ni anfaani to wa lara aayu ninu wọn la si ti ri pe o maa n jẹ ki ounjẹ tete da ninu eeyan. Awọn onimọ sọ pe aayu a maa se anfaani fun ọkan nitori kii jẹ ki oju isan ti ẹjẹ maa n gba di. Koda a gbọ pe ti eeyan ba mu aayu pẹlu miliki, a maa fun ni lokun paapa lati le fi se bi ọkunrin pẹlu obinrin rẹ. Die ree lara awọn oore to wa fun ara wa ti ba n lo aayu: Kikoju awọn kokoro aifojuri Aayu wa lara nkan tawọn to mọ nipa tewetegbo a maa lo lati fi koju aisan orisirisi. Bi o ba jẹ ti ka koju ikọ tabi ọfikin,aayu da pupọ. Lilo aayu a maa jẹ ki ikun jade daada ninu imu eeyan.Bẹẹ la tun gbọ pe o da fun egungun ara wa. Aayu a maa jẹ ki ọpọlọ ji pepe Bi eeyan ko ba ki n ranti nkan daada,a gbọ pe aayu ma n sọ ọpọlọ eeyan ji pepe pada. Kii jẹ ki awọn cell inu ọpọlọ ku ti a si tun maa fun eeyan lokun ati agbara paapa ti ẹni naa ba n se ere idaraya. Afẹfẹ oxygen to ba yẹ ko maa gba inu isan kọja daada, aayu maa n se iranwọ fun. Bi eeyan ba tu fẹran ko maa mu omi aayu saaju ki o to fi nkankan sinu laarọ eleyi a maa jẹ ki onitọun din sisanra ku. Awọn nkan wọnyi ni diẹ lara anfaani ti o wa lara aayu. Lori awọ ara wa, o se anfaani to pọ Awọn orisi aisan to maa n koju awọ ara eeyan naa a maa ri itọju ti onitọun ba lo aayu. Bo jẹ kokoro aifojuri bakiteria ni tabi fungal, aayu ni awọn eronja kan to le ba eeyan koju awọn kokoro aifojuri wọn yi. Ororo aayu sisẹ daada bi eeyan ba fẹ tọju lapalapa eela tabi awọn kokoro ara miran. Fawọn obinrin to fẹ ki irun wọn gun daada naa, wọn le lo aayu ti wọn peelo rẹ pẹlu oyin. Eleyi a maa mu ki irun gun daada tikii si jẹ ki irun maa ja. Lasiko yi o tọ ki a fi to ara wa leti pe bi eeyan ba jẹ aayu ni tutu, o maa n mu ki ẹnu eeyan maa bu ti. Nitori naa, arọwa si yin ni pe ki ẹ maa fọ ẹnu yin lẹyin ti ẹ ba jẹ aayu. | Uses of Garlic: Mọ̀ síi nípa àǹfàní tí lílo Aáyù lè fún ìlera ìwọ àti ẹbí rẹ Ilumọọka nkan isebẹ ti o loorun aladun ni Garlic tabi aayu jẹ. O kun fun eronja taa n pe ni Sulphur eyi to mu ki o maa se ara loore pupọ Orisirisi ni anfaani to wa lara aayu ninu wọn la si ti ri pe o maa n jẹ ki ounjẹ tete da ninu eeyan. Awọn onimọ sọ pe aayu a maa se anfaani fun ọkan nitori kii jẹ ki oju isan ti ẹjẹ maa n gba di. Koda a gbọ pe ti eeyan ba mu aayu pẹlu miliki, a maa fun ni lokun paapa lati le fi se bi ọkunrin pẹlu obinrin rẹ. Die ree lara awọn oore to wa fun ara wa ti ba n lo aayu: Kikoju awọn kokoro aifojuri Aayu wa lara nkan tawọn to mọ nipa tewetegbo a maa lo lati fi koju aisan orisirisi. Bi o ba jẹ ti ka koju ikọ tabi ọfikin,aayu da pupọ. Lilo aayu a maa jẹ ki ikun jade daada ninu imu eeyan.Bẹẹ la tun gbọ pe o da fun egungun ara wa. Aayu a maa jẹ ki ọpọlọ ji pepe Bi eeyan ko ba ki n ranti nkan daada,a gbọ pe aayu ma n sọ ọpọlọ eeyan ji pepe pada. Kii jẹ ki awọn cell inu ọpọlọ ku ti a si tun maa fun eeyan lokun ati agbara paapa ti ẹni naa ba n se ere idaraya. Afẹfẹ oxygen to ba yẹ ko maa gba inu isan kọja daada, aayu maa n se iranwọ fun. Bi eeyan ba tu fẹran ko maa mu omi aayu saaju ki o to fi nkankan sinu laarọ eleyi a maa jẹ ki onitọun din sisanra ku. Awọn nkan wọnyi ni diẹ lara anfaani ti o wa lara aayu. Lori awọ ara wa, o se anfaani to pọ Awọn orisi aisan to maa n koju awọ ara eeyan naa a maa ri itọju ti onitọun ba lo aayu. Bo jẹ kokoro aifojuri bakiteria ni tabi fungal, aayu ni awọn eronja kan to le ba eeyan koju awọn kokoro aifojuri wọn yi. Ororo aayu sisẹ daada bi eeyan ba fẹ tọju lapalapa eela tabi awọn kokoro ara miran. Fawọn obinrin to fẹ ki irun wọn gun daada naa, wọn le lo aayu ti wọn peelo rẹ pẹlu oyin. Eleyi a maa mu ki irun gun daada tikii si jẹ ki irun maa ja. Lasiko yi o tọ ki a fi to ara wa leti pe bi eeyan ba jẹ aayu ni tutu, o maa n mu ki ẹnu eeyan maa bu ti. Nitori naa, arọwa si yin ni pe ki ẹ maa fọ ẹnu yin lẹyin ti ẹ ba jẹ aayu. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-60013704 |
2health
| Ogun COVID-19 test: Ìjọba kéde ìlànà tuntun fún ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ ṣe ìdánwò àṣejáde | Ijọba ipinlẹ Ogun ti kede pe, eto ayẹwo arun Coronavirus ti di ọfẹ fawọn akẹkọọ ile ẹkọ girama to fẹ wọle pada. Ijọba gbe igbesẹ ọhun lẹyin idarudapọ to waye laarin awọn obi to ni ọmọ nile ẹkọ girama ati ijọba ipinlẹ Ogun lọjọ Aiku. Bakan naa ni ijọba pasẹ pe ki wọn pin aṣọ iboju ni ọfẹ fun gbogbo akẹkọọ to wa nipinlẹ naa, boya nile ẹkọ ijọba ni tabi ti aladani. Awọn ọrọ yii lo foju han ninu atẹjade kan ti gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun funra rẹ fọwọsi nirọlẹ ọjọ Aje. Gomina Abiodun ni oun kabamọ lori gbogbo idarudapọ to waye lori iṣẹlẹ naa. O ni ipese eto ẹkọ to ye kooro ati igbaye gbadun awọn akẹkọọ ipinlẹ naa lo jẹ ijọba oun l'ogun julọ.O tun han ninu atẹjade naa pe, ayẹwo awọn akẹkọọ lati mọ boya wọn ni arun Coronavirus kii ṣe dandan mọ fawọn akẹkọọjade to fẹ wọle pada sile ẹkọ. Ni ọjọ Aiku lawọn obi ati alagbatọ ni ipinlẹ Ogun fọn si igboro ilu Abẹokuta lati fi ẹhonu wọn han lori ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira ti ijọba ipinlẹ naa kede pe ki awọn akẹkọọ ileewe aladani o san fun ayẹwo kokoro arun COVID-19 ki wọn to lee wọle pada si ileewe. Lati igba ti iroyin naa ti jade sita lo ti n ṣe ọpọlọpọ ni haa-hin nitori idẹyẹsi naa. Bi ọpọlọpọ obi ṣe n pariwo pe bawo lọbọ ṣe ṣori ti inaki o ṣe to fi jẹ wi pe awọn akẹkọọ ileewe aladani ni yoo maa sanwo ayẹwo COVID-19 ki wọn to wọle pada sileewe. Bi o tilẹ jẹ wi pe ijọba ipinlẹ Ogun ninu atẹjade kan ti olubadamọran fun gomina ipinlẹ Ogun lori ọrọ Ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama, arabinrin Ronkẹ Soyọmbọ ṣalaye pe o di dandan fun awọn akẹkọ lati pese iwe ẹri ayẹwo COVID-19 wọn ki wọn to gbawọn si ileewe paapaajulọ awọn to ba wa ni ileegbe lawọn ileewe naa. Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Ogun ni gbogbo awọn ileewe aladani ni lati rii daju pe awọn akẹkọọ wọn ni iwe ẹri yii. Amọṣa loju opo Twitter ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC to jẹ ajọ kan ṣoṣo to laṣẹ lori eto ayẹwo fun kokoro arun naa, ọfẹ ni wọn kọ pe wọn n ṣe ayẹwo fun kokoro arun naa lorilẹede Naijiria. Ajọ naa ni ko si ibikibi ti wọn ti n fi owo ṣe ayẹwo COVID-19 fun ẹnikẹni lorilẹede Naijiria. Eyi lo mu ki ọpọ maa beere ibi ti ijọba ipinlẹ Ogun ti wa ri ẹdinwo owo ayẹwo kokoro arun COVID-19 ti wọn ni awọn n ṣe ati pe ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira ti wọn fẹ maa gba naa, owo ayẹwo ni ibudo wo ni? Amọṣa, ijọba ipinlẹ Ogun ni awọn eleto ilera kan lawọn fẹ lo ati pe awọn ti ba awọn eleto ilera naa sọrọ lati pese ayẹwo ọhun fun wọn ni ẹdinwo. Wayi o, awọn obi ti fariga pe awọn ko ni owo kankan lati san, bakan naa ni awọn ko tilẹ ni iwe ẹri kankan lati fi silẹ. Ninu ọrọ ti wọn ba BBC News Yoruba sọ, awọn obi kan ni awọn ko ni ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira lati san, ati pe awọn ko lee gba ki ọmọ awọn la wahala ti ayẹwo naa lee ko ba ironu awọn akẹkọọ. Awọn obi awọn akẹkọ ileewe aladani ni ipinlẹ Ogun ti fariga lori owo ayẹwo fun arun COVID-19 ti ijọba ipinlẹ naa bu fun awọn akẹkọ kọọkan ni sisan ki wọn to lee wọle pada sẹnu ẹkọ wọn ni ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ. Awọn obi awọn akẹkọọ ileewe aladani ọhun ke gbajare sita lasiko iwọde kan ti wọn ṣe ni ilu Abẹokuta lọjọ Aiku nibi ti wọn ti ni ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira ti ijọba ni ki awọn akẹkọọ ileewe aladani o san fun ayẹwo kokoro arun COVID-19 ko rọrun rara. Awọn obi naa ti wọn ya bo ileewosan MTR Specialist Hospital nibi ti wọn ti ni ayẹwo naa yoo ti maa waye ni awọn ko gbaradi fun irufẹ owo bẹẹ ni sisan ati pe bawo lọbọ ṣe ṣori ti inaki o ṣe to fi jẹ wi pe awọn akẹkọọ ileewe aladani nikan ni yoo maa san owo ayẹwo nigba ti awọn akẹkọọ ileewe ijọba ko ni san kọbọ fun ayẹwo kokoro arun naa. Wọn tun fi kun un pe ko si idi to fi yẹ ki ijọba kan owo naa ni ipa fun awọn akẹkọọ niwọn igba to jẹ wi pe wọn ti ni ki ileewe kọọkan o maa pese awọn ilana ati ohun elo fun ayẹwo awọn akẹkọọ ṣaaju iwọle wọn. Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin sọ, igbakeji alaga ẹgbẹ awọn obi ati olukọ PTA ni ipinlẹ Ogun, Alagba Kẹhinde Sanwo ṣalaye fawọn oniroyin pe ko yẹ ki ijọba maa dẹyẹsi awọn akẹkọọ ileewe aladani ati si awọn akẹkọọ ileewe ijọba nitori pe ọmọ ipinlẹ Ogun naa ni gbogbo wọn. Ninu ọrọ tirẹ, oludari eto ilera ni ipinlẹ Ogun, Dokita Olukayọde Soyinka ṣalaye pe ọrọ sisan ẹgbẹrun marundinlọgbọn owo ayẹwo kokoro COVID-19 ṣe ajeji si oun ati pe titi di asiko ti wọn n sọrọ naa, ọfẹ ni ayẹwo kokoro arun COVID-19 ni ipinlẹ Ogun . Ati pe, aṣẹ ti oun gba lọwọ kọmiṣọna ni lati wa nibi ayẹwo naa fun idẹra awọn akẹkọọ to ba wa ṣe ayẹwo nibẹ. | Ogun COVID-19 test: Ìjọba kéde ìlànà tuntun fún ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ ṣe ìdánwò àṣejáde Ijọba ipinlẹ Ogun ti kede pe, eto ayẹwo arun Coronavirus ti di ọfẹ fawọn akẹkọọ ile ẹkọ girama to fẹ wọle pada. Ijọba gbe igbesẹ ọhun lẹyin idarudapọ to waye laarin awọn obi to ni ọmọ nile ẹkọ girama ati ijọba ipinlẹ Ogun lọjọ Aiku. Bakan naa ni ijọba pasẹ pe ki wọn pin aṣọ iboju ni ọfẹ fun gbogbo akẹkọọ to wa nipinlẹ naa, boya nile ẹkọ ijọba ni tabi ti aladani. Awọn ọrọ yii lo foju han ninu atẹjade kan ti gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun funra rẹ fọwọsi nirọlẹ ọjọ Aje. Gomina Abiodun ni oun kabamọ lori gbogbo idarudapọ to waye lori iṣẹlẹ naa. O ni ipese eto ẹkọ to ye kooro ati igbaye gbadun awọn akẹkọọ ipinlẹ naa lo jẹ ijọba oun l'ogun julọ.O tun han ninu atẹjade naa pe, ayẹwo awọn akẹkọọ lati mọ boya wọn ni arun Coronavirus kii ṣe dandan mọ fawọn akẹkọọjade to fẹ wọle pada sile ẹkọ. Ni ọjọ Aiku lawọn obi ati alagbatọ ni ipinlẹ Ogun fọn si igboro ilu Abẹokuta lati fi ẹhonu wọn han lori ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira ti ijọba ipinlẹ naa kede pe ki awọn akẹkọọ ileewe aladani o san fun ayẹwo kokoro arun COVID-19 ki wọn to lee wọle pada si ileewe. Lati igba ti iroyin naa ti jade sita lo ti n ṣe ọpọlọpọ ni haa-hin nitori idẹyẹsi naa. Bi ọpọlọpọ obi ṣe n pariwo pe bawo lọbọ ṣe ṣori ti inaki o ṣe to fi jẹ wi pe awọn akẹkọọ ileewe aladani ni yoo maa sanwo ayẹwo COVID-19 ki wọn to wọle pada sileewe. Bi o tilẹ jẹ wi pe ijọba ipinlẹ Ogun ninu atẹjade kan ti olubadamọran fun gomina ipinlẹ Ogun lori ọrọ Ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama, arabinrin Ronkẹ Soyọmbọ ṣalaye pe o di dandan fun awọn akẹkọ lati pese iwe ẹri ayẹwo COVID-19 wọn ki wọn to gbawọn si ileewe paapaajulọ awọn to ba wa ni ileegbe lawọn ileewe naa. Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Ogun ni gbogbo awọn ileewe aladani ni lati rii daju pe awọn akẹkọọ wọn ni iwe ẹri yii. Amọṣa loju opo Twitter ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC to jẹ ajọ kan ṣoṣo to laṣẹ lori eto ayẹwo fun kokoro arun naa, ọfẹ ni wọn kọ pe wọn n ṣe ayẹwo fun kokoro arun naa lorilẹede Naijiria. Ajọ naa ni ko si ibikibi ti wọn ti n fi owo ṣe ayẹwo COVID-19 fun ẹnikẹni lorilẹede Naijiria. Eyi lo mu ki ọpọ maa beere ibi ti ijọba ipinlẹ Ogun ti wa ri ẹdinwo owo ayẹwo kokoro arun COVID-19 ti wọn ni awọn n ṣe ati pe ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira ti wọn fẹ maa gba naa, owo ayẹwo ni ibudo wo ni? Amọṣa, ijọba ipinlẹ Ogun ni awọn eleto ilera kan lawọn fẹ lo ati pe awọn ti ba awọn eleto ilera naa sọrọ lati pese ayẹwo ọhun fun wọn ni ẹdinwo. Wayi o, awọn obi ti fariga pe awọn ko ni owo kankan lati san, bakan naa ni awọn ko tilẹ ni iwe ẹri kankan lati fi silẹ. Ninu ọrọ ti wọn ba BBC News Yoruba sọ, awọn obi kan ni awọn ko ni ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira lati san, ati pe awọn ko lee gba ki ọmọ awọn la wahala ti ayẹwo naa lee ko ba ironu awọn akẹkọọ. Awọn obi awọn akẹkọ ileewe aladani ni ipinlẹ Ogun ti fariga lori owo ayẹwo fun arun COVID-19 ti ijọba ipinlẹ naa bu fun awọn akẹkọ kọọkan ni sisan ki wọn to lee wọle pada sẹnu ẹkọ wọn ni ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ. Awọn obi awọn akẹkọọ ileewe aladani ọhun ke gbajare sita lasiko iwọde kan ti wọn ṣe ni ilu Abẹokuta lọjọ Aiku nibi ti wọn ti ni ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira ti ijọba ni ki awọn akẹkọọ ileewe aladani o san fun ayẹwo kokoro arun COVID-19 ko rọrun rara. Awọn obi naa ti wọn ya bo ileewosan MTR Specialist Hospital nibi ti wọn ti ni ayẹwo naa yoo ti maa waye ni awọn ko gbaradi fun irufẹ owo bẹẹ ni sisan ati pe bawo lọbọ ṣe ṣori ti inaki o ṣe to fi jẹ wi pe awọn akẹkọọ ileewe aladani nikan ni yoo maa san owo ayẹwo nigba ti awọn akẹkọọ ileewe ijọba ko ni san kọbọ fun ayẹwo kokoro arun naa. Wọn tun fi kun un pe ko si idi to fi yẹ ki ijọba kan owo naa ni ipa fun awọn akẹkọọ niwọn igba to jẹ wi pe wọn ti ni ki ileewe kọọkan o maa pese awọn ilana ati ohun elo fun ayẹwo awọn akẹkọọ ṣaaju iwọle wọn. Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin sọ, igbakeji alaga ẹgbẹ awọn obi ati olukọ PTA ni ipinlẹ Ogun, Alagba Kẹhinde Sanwo ṣalaye fawọn oniroyin pe ko yẹ ki ijọba maa dẹyẹsi awọn akẹkọọ ileewe aladani ati si awọn akẹkọọ ileewe ijọba nitori pe ọmọ ipinlẹ Ogun naa ni gbogbo wọn. Ninu ọrọ tirẹ, oludari eto ilera ni ipinlẹ Ogun, Dokita Olukayọde Soyinka ṣalaye pe ọrọ sisan ẹgbẹrun marundinlọgbọn owo ayẹwo kokoro COVID-19 ṣe ajeji si oun ati pe titi di asiko ti wọn n sọrọ naa, ọfẹ ni ayẹwo kokoro arun COVID-19 ni ipinlẹ Ogun . Ati pe, aṣẹ ti oun gba lọwọ kọmiṣọna ni lati wa nibi ayẹwo naa fun idẹra awọn akẹkọọ to ba wa ṣe ayẹwo nibẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-53628080 |
4religion
| Jesus in Kenya:Ta ni ọkùnrin tí wọ́n ń pè ní ayédèrú Jesu yìí gan an? | Ọpọ aworan ati fidio to n ṣafihan ọkunrin kan to wo aṣọ bi Jesu Kristi, ti lu oju ayelujara pa lẹnu ọjọ mẹta yii kaakiri ilẹ Afirika. Ṣugbọn ta ni ọkunrin yii to n pe ara rẹ ni Jesu gan an, ati pe kinni o n ṣe kaakiri ilẹ adulawọ? Ọpọ eeyan lo ti n pin aworan ati fọnran ọkunrin yii lori ayelujara, koda aṣofin kan lorilẹede South Africa, Julius Malema sọ pe, alufa ijọ kan lorilẹede ọhun gbalejo Jesu yii, lati wa ṣe iwaasu ninu ijọ rẹ. Amọ, awọn aworan to lu ayelujara pa ọhun wa lati ibi ayẹyẹ kan niluu Kiserian, lagbegbe Nairobi lorilẹede Kenya. Orukọ ọkunrin eke Jesu yii ni Michael Job, o jẹ ọmọ orilẹede Amẹrika. Oniwaasu ni, bakan naa lọ jẹ oṣere tiata. Ilu Orlando nipinlẹ Florida ni ọkunrin ọhun n gbe, nibi to ti n ṣe bii Jesu. Isọ ti wọn ti n ta aga ijoko ati nnkan ọgbin lo wa ninu fidio to fi sita lori oju opo Facebook rẹ. Ọpọ eeyan lori ayelujara lo ti n fi awọn aworan ọkunrin yii ṣe ẹfẹ ati bi awọn alufa ijọ kan nilẹ Afirika, ṣe maa n ṣe iṣẹ iyanu. Ọkan lara awọn aworan yii ṣafihan bi alufa kan lorilẹede Kenyan sẹ sọ wi pe, oun ri Jesu to rin loju popo ni Kenya. Michael Job ṣeleri wi pe, oun n ṣiṣẹ iyanu ati imularada ninu awọn fọnran iwaasu rẹ lorilẹede Kenya, bo tilẹ jẹ pe ọpọ lo koro oju si ọrọ yii. Kii ṣe igba akọkọ ree ti Ọgbẹni Job wa si ilẹ Afirika, o ti wa si orilẹede Togo nibẹrẹ ọdun yii ṣugbọn ko wọ iru aṣọ bayii nigba naa, kootu lo wọ. | Jesus in Kenya:Ta ni ọkùnrin tí wọ́n ń pè ní ayédèrú Jesu yìí gan an? Ọpọ aworan ati fidio to n ṣafihan ọkunrin kan to wo aṣọ bi Jesu Kristi, ti lu oju ayelujara pa lẹnu ọjọ mẹta yii kaakiri ilẹ Afirika. Ṣugbọn ta ni ọkunrin yii to n pe ara rẹ ni Jesu gan an, ati pe kinni o n ṣe kaakiri ilẹ adulawọ? Ọpọ eeyan lo ti n pin aworan ati fọnran ọkunrin yii lori ayelujara, koda aṣofin kan lorilẹede South Africa, Julius Malema sọ pe, alufa ijọ kan lorilẹede ọhun gbalejo Jesu yii, lati wa ṣe iwaasu ninu ijọ rẹ. Amọ, awọn aworan to lu ayelujara pa ọhun wa lati ibi ayẹyẹ kan niluu Kiserian, lagbegbe Nairobi lorilẹede Kenya. Orukọ ọkunrin eke Jesu yii ni Michael Job, o jẹ ọmọ orilẹede Amẹrika. Oniwaasu ni, bakan naa lọ jẹ oṣere tiata. Ilu Orlando nipinlẹ Florida ni ọkunrin ọhun n gbe, nibi to ti n ṣe bii Jesu. Isọ ti wọn ti n ta aga ijoko ati nnkan ọgbin lo wa ninu fidio to fi sita lori oju opo Facebook rẹ. Ọpọ eeyan lori ayelujara lo ti n fi awọn aworan ọkunrin yii ṣe ẹfẹ ati bi awọn alufa ijọ kan nilẹ Afirika, ṣe maa n ṣe iṣẹ iyanu. Ọkan lara awọn aworan yii ṣafihan bi alufa kan lorilẹede Kenyan sẹ sọ wi pe, oun ri Jesu to rin loju popo ni Kenya. Michael Job ṣeleri wi pe, oun n ṣiṣẹ iyanu ati imularada ninu awọn fọnran iwaasu rẹ lorilẹede Kenya, bo tilẹ jẹ pe ọpọ lo koro oju si ọrọ yii. Kii ṣe igba akọkọ ree ti Ọgbẹni Job wa si ilẹ Afirika, o ti wa si orilẹede Togo nibẹrẹ ọdun yii ṣugbọn ko wọ iru aṣọ bayii nigba naa, kootu lo wọ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-49167847 |
1entertainment
| Nkechi Blessing: Ọ̀pọ̀ ọ̀gá òṣèré ló ń bèèrè ìbálòpọ̀, kí obìrin tó gba eré tíátà lọ́wọ́ wọn | Yoruba ni bi ọrọ ba se n pẹ nilẹ, gbigbọn ni yoo maa gbọn si. Bẹẹ ni ọrọ ri nipa isẹlẹ to waye si Baba Ijesha, ẹni ti wọn fi ẹsun sise asemase pẹlu ọmọkan kan, to si n jẹjọ lọwọ. Lọtẹ yii, ọkan lara awọn osere tiata lobinrin, ti ọrọ naa ka lara pupọ, Nkechi Blessing Sunday tun ti sọrọ lẹẹkan si nipa isẹlẹ naa. Nkechi, lasiko to n kopa lori ifọrọwanilẹnuwo kan lori Instagram pẹlu Jude Jideonwo salaye idi ti ọrọ naa se ka lara. Ninu alaye rẹ, Osere tiata lobinrin naa ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni oun wa nigba ti ọkunrin kan fẹ fi tipa ba oun lopọ. O salaye siwaju pe oun finu wenu nigba naa ni, amọ Ọlọrun nikan ni ko jẹ ki oun jẹ iwọ. "Mo sọ fun ẹgbọn mi obinrin kan pe n ko ti mọ ọkunrin ati pe ko si akọ kankan to tii si mo ni asọ wo ri amọ o ni irọ ni mo n pa. Nigba naa, ọti bia ni iya mi maa n ta, ti mo si maa n jo gan. Lọjọ kan ni anti mi yii wa ni ka jọ lọ sile ọrẹkunrin rẹ, ti mo si tẹle amọ n ko mọ pe o tan mi lọ sibẹ ni lati fidi ootọ mulẹ boya lootọ ni n ko mọ ọkunrin. Ko pẹ ta de ibẹ ni wọn fun mi ni ọti ẹlẹrindodo, ti mo si mu, ti anti mi si ni oun fẹ sare de ibi kan, to si ku emi ati ọrẹkunrin rẹ ninu ile." Nkechi tẹsiwaju pe bi anti oun se jade ni ọkunrin naa n gbe sunmọ oun, to si wa joko si ẹgbẹ oun pẹki-pẹki. O ni ni kete ni skan oun lọ sibi ọrọ ajọsọ oun ati anti naa nipa pe oun ko mọ skunrin, ti ara si bẹrẹ si fu oun nitori oun ti ni oye nipa ibalopọ nigba naa. O fikun pe ẹrun bẹrẹ si ni ba oun, ti oun si dide pe oun n lọ amọ ti ọkunrin naa dide lati di oun lọwọ mu, to si ni oun ko le lọ amọ ti oun yari mọ lọwọ. Nkechi ni igba yii ni oun wa beere lọwọ ọkunrin naa pe se o fẹ fi tipa ba oun ni ajọsepọ ni? Eyi si lo ni o ya lẹnu pupọ, ti oun si ri ọna sa jade nibẹ. "O yẹ ki wọn se idajọ iku fun awọn afipabanilopọ ni, ko si yẹ ki wọn maa gbe wọn lọ sile ẹjọ, ni kete ti ọkunrin kan ba ti fipa ba obinrin kan lopọ, ni ki wọn lu pa." Ninu ifọrọwerọ naa ni Nkechi tun ti si agbada lori ọrọ kan to ni se pẹlu ipa ti ẹgbẹ osere TAMPAN ko lasiko ti isẹlẹ Baba Ijesha waye. Nkechi ni lootọ ni oun bu ẹnu atẹ lu awọn asaaju ẹgbẹ osere naa, ti Alagba Bolaji Amusan, ti ọpọ eeyan mọ si Mr Latin ko sodi nitori pe wọn ko tete sọrọ lori isẹlẹ naa. Amọ o ni nigba to ya ni Latin se fidio kan pe awọn ko le le Baba Ijesha kuro ninu ẹgbẹ TAMPAN nitori kii se ọmọ ẹgbẹ awọn, ti awọn si fara mọ ohun to sọ. "Amọ tẹ ba fẹ mọ idi ti ọpọ wọn se dakẹ jẹ nigba ti ọrọ Baba Ijesha sẹlẹ, idi ni pe iru kan naa ni wọn. Ko fẹ ẹ si ọga elere kankan ninu ẹgbẹ TAMPAN to le sare jade sọrọ lori ẹsun ifipabanilopọ nitori ọpọ wọn ni wọn maa n kọkọ beere lati tu obinrin ni asọ wo, saaju ki wọn to fun ni ipa kan lati ko ninu ere. Bi wọn ba si fi sare sọrọ pẹrẹ, gbogbo awọn eeyan ti wọn ti fi ere gba asọ lara wọn ni yoo jade lati wa fi ẹsun kan awọn naa. Lana kan abi omiran, gbogbo wọn ni wọn jẹbi ẹsun iwa ti Baba Ijesha hu, ti ẹnu wọn ko si le to ọrọ. Wọn yoo fi ọwọ gbaya pe ti osere binrin kan ko ba sun pẹlu awọn, awọn ko ni gbe ipo kan fun ninu ere ti wsn ba fẹ se. Nkechi Blessing wa ni isẹlẹ to ti waye saaju si oun lo mu ki oun gba ọrọ ẹsun Baba Ijesha naa kanri. | Nkechi Blessing: Ọ̀pọ̀ ọ̀gá òṣèré ló ń bèèrè ìbálòpọ̀, kí obìrin tó gba eré tíátà lọ́wọ́ wọn Yoruba ni bi ọrọ ba se n pẹ nilẹ, gbigbọn ni yoo maa gbọn si. Bẹẹ ni ọrọ ri nipa isẹlẹ to waye si Baba Ijesha, ẹni ti wọn fi ẹsun sise asemase pẹlu ọmọkan kan, to si n jẹjọ lọwọ. Lọtẹ yii, ọkan lara awọn osere tiata lobinrin, ti ọrọ naa ka lara pupọ, Nkechi Blessing Sunday tun ti sọrọ lẹẹkan si nipa isẹlẹ naa. Nkechi, lasiko to n kopa lori ifọrọwanilẹnuwo kan lori Instagram pẹlu Jude Jideonwo salaye idi ti ọrọ naa se ka lara. Ninu alaye rẹ, Osere tiata lobinrin naa ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni oun wa nigba ti ọkunrin kan fẹ fi tipa ba oun lopọ. O salaye siwaju pe oun finu wenu nigba naa ni, amọ Ọlọrun nikan ni ko jẹ ki oun jẹ iwọ. "Mo sọ fun ẹgbọn mi obinrin kan pe n ko ti mọ ọkunrin ati pe ko si akọ kankan to tii si mo ni asọ wo ri amọ o ni irọ ni mo n pa. Nigba naa, ọti bia ni iya mi maa n ta, ti mo si maa n jo gan. Lọjọ kan ni anti mi yii wa ni ka jọ lọ sile ọrẹkunrin rẹ, ti mo si tẹle amọ n ko mọ pe o tan mi lọ sibẹ ni lati fidi ootọ mulẹ boya lootọ ni n ko mọ ọkunrin. Ko pẹ ta de ibẹ ni wọn fun mi ni ọti ẹlẹrindodo, ti mo si mu, ti anti mi si ni oun fẹ sare de ibi kan, to si ku emi ati ọrẹkunrin rẹ ninu ile." Nkechi tẹsiwaju pe bi anti oun se jade ni ọkunrin naa n gbe sunmọ oun, to si wa joko si ẹgbẹ oun pẹki-pẹki. O ni ni kete ni skan oun lọ sibi ọrọ ajọsọ oun ati anti naa nipa pe oun ko mọ skunrin, ti ara si bẹrẹ si fu oun nitori oun ti ni oye nipa ibalopọ nigba naa. O fikun pe ẹrun bẹrẹ si ni ba oun, ti oun si dide pe oun n lọ amọ ti ọkunrin naa dide lati di oun lọwọ mu, to si ni oun ko le lọ amọ ti oun yari mọ lọwọ. Nkechi ni igba yii ni oun wa beere lọwọ ọkunrin naa pe se o fẹ fi tipa ba oun ni ajọsepọ ni? Eyi si lo ni o ya lẹnu pupọ, ti oun si ri ọna sa jade nibẹ. "O yẹ ki wọn se idajọ iku fun awọn afipabanilopọ ni, ko si yẹ ki wọn maa gbe wọn lọ sile ẹjọ, ni kete ti ọkunrin kan ba ti fipa ba obinrin kan lopọ, ni ki wọn lu pa." Ninu ifọrọwerọ naa ni Nkechi tun ti si agbada lori ọrọ kan to ni se pẹlu ipa ti ẹgbẹ osere TAMPAN ko lasiko ti isẹlẹ Baba Ijesha waye. Nkechi ni lootọ ni oun bu ẹnu atẹ lu awọn asaaju ẹgbẹ osere naa, ti Alagba Bolaji Amusan, ti ọpọ eeyan mọ si Mr Latin ko sodi nitori pe wọn ko tete sọrọ lori isẹlẹ naa. Amọ o ni nigba to ya ni Latin se fidio kan pe awọn ko le le Baba Ijesha kuro ninu ẹgbẹ TAMPAN nitori kii se ọmọ ẹgbẹ awọn, ti awọn si fara mọ ohun to sọ. "Amọ tẹ ba fẹ mọ idi ti ọpọ wọn se dakẹ jẹ nigba ti ọrọ Baba Ijesha sẹlẹ, idi ni pe iru kan naa ni wọn. Ko fẹ ẹ si ọga elere kankan ninu ẹgbẹ TAMPAN to le sare jade sọrọ lori ẹsun ifipabanilopọ nitori ọpọ wọn ni wọn maa n kọkọ beere lati tu obinrin ni asọ wo, saaju ki wọn to fun ni ipa kan lati ko ninu ere. Bi wọn ba si fi sare sọrọ pẹrẹ, gbogbo awọn eeyan ti wọn ti fi ere gba asọ lara wọn ni yoo jade lati wa fi ẹsun kan awọn naa. Lana kan abi omiran, gbogbo wọn ni wọn jẹbi ẹsun iwa ti Baba Ijesha hu, ti ẹnu wọn ko si le to ọrọ. Wọn yoo fi ọwọ gbaya pe ti osere binrin kan ko ba sun pẹlu awọn, awọn ko ni gbe ipo kan fun ninu ere ti wsn ba fẹ se. Nkechi Blessing wa ni isẹlẹ to ti waye saaju si oun lo mu ki oun gba ọrọ ẹsun Baba Ijesha naa kanri. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-58613853 |
1entertainment
| Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa adẹ́rínpòṣónú, Peteru tó jáde láyé | Gbajugbaja adẹrinpoṣonu to tun jẹ sọrọsọrọ lori redio, Oluwatobi Owomoyela, ti ọpọ mọ si Peteru ti jade laye. Ọjọbọ ọṣe yii ni adẹrinpoṣonu naa fi aye silẹ lẹni ọdun marundinlogoji. Iroyin ni aisan jẹjẹrẹ ‘colon cancer’ lo mu ẹmi oloogbe naa lọ, ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ kaakiri Naijiria lo si ti bẹrẹ si n ṣedaro iku rẹ. Ṣaaju iku rẹ, Peteru jẹ ọkan lara awọn adẹrinpọsọnu ti irawọ rẹ ṣẹṣẹ n tan, paapaa ni iha Gusu iwọ oorun Naijiria. Yatọ si pe o n ṣe iṣe adẹrinpoṣonu, o tun jẹ sọrọsọrọ lori redio niluu Ibadan, o tu maa n ṣiṣẹ adari ayẹyẹ. Ninu atẹjade kan loju opo Instagram rẹ, oṣere tiata Yoruba, Muyiwa Ademola pin iroyin nipa iku oloogbe naa, to si fi fidio kan sibẹ ni iranti rtẹ. Ademola ni “Iroyin iku rẹ ṣoro fun mi lati gba... bawo ni irufẹ eeyan rere bayii ṣe maa ku?” Lẹyin naa lo ni “Ẹ jọwọ ẹ jẹ ka maa ṣe daadaa si ọmọlakeji wa o, nitori a ko mọ ohun ti ẹnikẹni n la kọja.” “Mo gbọ pe arun jẹjẹrẹ lo pa Peteru. O n la irufẹ nnkan bayẹn kọja o si maa n rẹrin ni gbogbo igba.” Yatọ si Muyiwa Ademola, ọpọ awọn gbajumọ mii lo ti bẹrẹ si n ṣedaro oloogbe ọhun. Lara wọn ni Ọmọwe Jaiye Kuti, ti ọpọ mọ si Jayeola ni mo n jẹ, Wolii Agba, Princess Comedian, ati bẹẹ bẹẹ lọ. | Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa adẹ́rínpòṣónú, Peteru tó jáde láyé Gbajugbaja adẹrinpoṣonu to tun jẹ sọrọsọrọ lori redio, Oluwatobi Owomoyela, ti ọpọ mọ si Peteru ti jade laye. Ọjọbọ ọṣe yii ni adẹrinpoṣonu naa fi aye silẹ lẹni ọdun marundinlogoji. Iroyin ni aisan jẹjẹrẹ ‘colon cancer’ lo mu ẹmi oloogbe naa lọ, ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ kaakiri Naijiria lo si ti bẹrẹ si n ṣedaro iku rẹ. Ṣaaju iku rẹ, Peteru jẹ ọkan lara awọn adẹrinpọsọnu ti irawọ rẹ ṣẹṣẹ n tan, paapaa ni iha Gusu iwọ oorun Naijiria. Yatọ si pe o n ṣe iṣe adẹrinpoṣonu, o tun jẹ sọrọsọrọ lori redio niluu Ibadan, o tu maa n ṣiṣẹ adari ayẹyẹ. Ninu atẹjade kan loju opo Instagram rẹ, oṣere tiata Yoruba, Muyiwa Ademola pin iroyin nipa iku oloogbe naa, to si fi fidio kan sibẹ ni iranti rtẹ. Ademola ni “Iroyin iku rẹ ṣoro fun mi lati gba... bawo ni irufẹ eeyan rere bayii ṣe maa ku?” Lẹyin naa lo ni “Ẹ jọwọ ẹ jẹ ka maa ṣe daadaa si ọmọlakeji wa o, nitori a ko mọ ohun ti ẹnikẹni n la kọja.” “Mo gbọ pe arun jẹjẹrẹ lo pa Peteru. O n la irufẹ nnkan bayẹn kọja o si maa n rẹrin ni gbogbo igba.” Yatọ si Muyiwa Ademola, ọpọ awọn gbajumọ mii lo ti bẹrẹ si n ṣedaro oloogbe ọhun. Lara wọn ni Ọmọwe Jaiye Kuti, ti ọpọ mọ si Jayeola ni mo n jẹ, Wolii Agba, Princess Comedian, ati bẹẹ bẹẹ lọ. | https://www.bbc.com/yoruba/articles/cp36118mkp1o |
3politics
| Ahmed Gulak's death: Àwọn jàndùkú agbébọn ṣekúpa Ahmed Gulak, olùdàmọ́ràn Goodluck Jonathan | Awọn janduku agbebọn ti ṣekupa Ahmed Gulak tii ṣe oluranlọwọ aarẹ ana orilẹ-ede Naijiria, Goodluck Jonathan. Ilu Owerri nipinlẹ Imo ni wọn ti sọ pe wọn yinbọn pa Gulak. Gulak n rinrin ajo lati Abuja si Owerri lalẹ ọjọ Abamẹta ki o to ṣagbako iku ojiji lọna. A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun laipẹ. | Ahmed Gulak's death: Àwọn jàndùkú agbébọn ṣekúpa Ahmed Gulak, olùdàmọ́ràn Goodluck Jonathan Awọn janduku agbebọn ti ṣekupa Ahmed Gulak tii ṣe oluranlọwọ aarẹ ana orilẹ-ede Naijiria, Goodluck Jonathan. Ilu Owerri nipinlẹ Imo ni wọn ti sọ pe wọn yinbọn pa Gulak. Gulak n rinrin ajo lati Abuja si Owerri lalẹ ọjọ Abamẹta ki o to ṣagbako iku ojiji lọna. A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun laipẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-57297676 |
2health
| Postpartum vaginal steaming: Njẹ anfààní wà nínú fífi omi gbóná jó ojú ara lẹ́yìn ìbímọ? | Lẹyin ti obinrin ba bimọ tan, ibeere nla ti ọpọ a maa beere ni pe se ile ọmọ obinrin ti iyipada ti de ba, njẹ o le sun ki pada si bo se wa tẹlẹ? Gbogbo obinrin ni eleyi maa n sẹlẹ si nitori bi eledua ti se sẹda ara wa nuu ni. Ni idahun si ibeere yi, lootọ a maa sun pada sipo. Amọ arabinrin Veronica Azeru sọ pe o ni awọn nkan ti eeyan le se ti yoo mu ki ara obinrin paapa ile ọmọ pada si bo se wa tẹlẹ lẹyin to ba bimọ tan. 'Ojú ara méjì ni mo ní, wọ́n sì bí i mọ́ mí ni' Wo ewu tó wà nínú fífi ọ̀sẹ̀ fọ ojú ara fún ọkùnrin àti obìnrin ‘Pussypedia’ rèé, ojú òpó tó ń mú àdínkù bá ìṣòro ìmọ̀ nípa ẹ̀yà ara obìnrin Wo ohun tó yẹ kí o ṣe sí ojú abẹ́ rẹ, ''vagina'' lẹ́yìn ìbálòpọ̀ Olugbẹbi yi ni lootọ lawọn nkan maa n sẹlẹ si awọn to ba pade inira lasiko igbẹbi tori naa si lawọn fi n se itọju fun wọn eyi to yatọ. Lara nkan ti wọn maa n se fawọn obinrin to sẹsẹ bimọ tan ni pe wọn a maa ni ki wọn joko lori omi gbigbona ki wọn baa le gba ooru gnbigbona yi si abẹ wọn. Bakan naa wọn a maa ni ki wọn mu ọbẹ alata,pepper soup lawọn agbegbe kan ni Naijiria. Azeru sọ pe"Irinaj o ni oyun jẹ bẹẹ lo si maa n tẹsiwaju pẹlu itọju lẹyin ibimọ.Nkan to kan yatọ ni pe asiko ti onikaluku maa n lo yatọ si ara wọn'' Lẹyin ibimọ, ọpọ obinrin a maa ri inira. Sugbọn irora yi a maa yatọ laarin awọn to bimọ lalae se isẹ abẹ ati awọn to se isẹ abẹ. Monica Azeru to n sisẹ olugbẹbi ni Port Harcourt, sọ pe idi ree tawọn fi n seto itọju olomigbona. ''Omi to lọwọrọ yi maa n mu ki awọn nkankan to ba si sẹku lara obinrin jade lọwọ ẹrọ''. À ń wá àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ajá, ẹ kàn sí wa tí ẹ bá mọ̀ wọ́n - ọlọ́pàá Naijiria Owó ńlá ti fẹ́ ṣe mí léṣe ní London o! Ẹ wá wo bí mo ṣe ń jayé orí mi bíi skódà - Portable Ìjọba gbé ilẹ ìtura tì pa lẹ́yìn tí wọ́n gé ẹ̀yà ara obìnrin kan lọ níbẹ̀ Sultan kéde ọjọ́ Ajé gẹ̀gẹ́ bíi ọjọ́ ọdún ìtúnu àwẹ̀ ní Naijiria Ǹkan tí èmi àti Alaafin jọ ṣe sílẹ́ lórí àṣà Yorùbá kìí ṣe kèrémí - Òyìnbó òṣìṣẹ́ O ni lootọ lawọn oogun oyinbo to le se isẹ yi wa sugbọn awọn obinrin nifẹ si ilana olomi gbona yi. ''Ilana yi maa n jẹ ki ẹjẹ jade daada.A maa jẹ ki ara bọ sipo pada kiakia.'' "Omi to lọwọrọ ati pepper soup lẹyin ibimọ maa n jẹ ki ile ọmọ sunki ti a si tun maa fọ ara abiyamọ'' Oogun lilo dara ṣa? Dokita Rosemary Ogu,onimọ itọju aboyun sọ pe o dara ki alaboyun gba imọran lọdọ awọn onimọ. O tun fero ọkan rẹ han lori bi awọn obinrin se le sesi ko kokoro aifojuri ti wọn ko ba seto itọju omi gbona daada. Ọjọgbọn Ogu ni : " Bi wọn ba lo omi gbona lẹyin ẹbi ni nkan bi ogun si ọgbọn isẹju ko buru sugbọn ko yẹ ki omi naa gbona ju.'' Lori wiwọ ikun abiyamọ o ni''A gba awọn obinrin ni imọran ki wọn jawọ nidi fifi omi gbona wọ ikun saaju ati lẹyin ibimọ,isesi ti ko dara to ni o si yẹ ki wọn jawọ nibẹ'' Onimọ yi tun gba awọn obinrin ni imọran lati ma se maa lọ si ọdọ awọn agbẹbi abẹle nitori ofin orileede Naijiria ko faaye gba wọn. "Nkan ti wọn n se lodi si ofin isẹ wọn si ti sokunfa iku ọpọ obinrin'' "Wọn kii se akọsẹmọsẹ bẹẹ wọn ko gbẹkọ nipa itọju alaboyun ni pataki bi nkan ba fẹ yiwọ'' | Postpartum vaginal steaming: Njẹ anfààní wà nínú fífi omi gbóná jó ojú ara lẹ́yìn ìbímọ? Lẹyin ti obinrin ba bimọ tan, ibeere nla ti ọpọ a maa beere ni pe se ile ọmọ obinrin ti iyipada ti de ba, njẹ o le sun ki pada si bo se wa tẹlẹ? Gbogbo obinrin ni eleyi maa n sẹlẹ si nitori bi eledua ti se sẹda ara wa nuu ni. Ni idahun si ibeere yi, lootọ a maa sun pada sipo. Amọ arabinrin Veronica Azeru sọ pe o ni awọn nkan ti eeyan le se ti yoo mu ki ara obinrin paapa ile ọmọ pada si bo se wa tẹlẹ lẹyin to ba bimọ tan. 'Ojú ara méjì ni mo ní, wọ́n sì bí i mọ́ mí ni' Wo ewu tó wà nínú fífi ọ̀sẹ̀ fọ ojú ara fún ọkùnrin àti obìnrin ‘Pussypedia’ rèé, ojú òpó tó ń mú àdínkù bá ìṣòro ìmọ̀ nípa ẹ̀yà ara obìnrin Wo ohun tó yẹ kí o ṣe sí ojú abẹ́ rẹ, ''vagina'' lẹ́yìn ìbálòpọ̀ Olugbẹbi yi ni lootọ lawọn nkan maa n sẹlẹ si awọn to ba pade inira lasiko igbẹbi tori naa si lawọn fi n se itọju fun wọn eyi to yatọ. Lara nkan ti wọn maa n se fawọn obinrin to sẹsẹ bimọ tan ni pe wọn a maa ni ki wọn joko lori omi gbigbona ki wọn baa le gba ooru gnbigbona yi si abẹ wọn. Bakan naa wọn a maa ni ki wọn mu ọbẹ alata,pepper soup lawọn agbegbe kan ni Naijiria. Azeru sọ pe"Irinaj o ni oyun jẹ bẹẹ lo si maa n tẹsiwaju pẹlu itọju lẹyin ibimọ.Nkan to kan yatọ ni pe asiko ti onikaluku maa n lo yatọ si ara wọn'' Lẹyin ibimọ, ọpọ obinrin a maa ri inira. Sugbọn irora yi a maa yatọ laarin awọn to bimọ lalae se isẹ abẹ ati awọn to se isẹ abẹ. Monica Azeru to n sisẹ olugbẹbi ni Port Harcourt, sọ pe idi ree tawọn fi n seto itọju olomigbona. ''Omi to lọwọrọ yi maa n mu ki awọn nkankan to ba si sẹku lara obinrin jade lọwọ ẹrọ''. À ń wá àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ajá, ẹ kàn sí wa tí ẹ bá mọ̀ wọ́n - ọlọ́pàá Naijiria Owó ńlá ti fẹ́ ṣe mí léṣe ní London o! Ẹ wá wo bí mo ṣe ń jayé orí mi bíi skódà - Portable Ìjọba gbé ilẹ ìtura tì pa lẹ́yìn tí wọ́n gé ẹ̀yà ara obìnrin kan lọ níbẹ̀ Sultan kéde ọjọ́ Ajé gẹ̀gẹ́ bíi ọjọ́ ọdún ìtúnu àwẹ̀ ní Naijiria Ǹkan tí èmi àti Alaafin jọ ṣe sílẹ́ lórí àṣà Yorùbá kìí ṣe kèrémí - Òyìnbó òṣìṣẹ́ O ni lootọ lawọn oogun oyinbo to le se isẹ yi wa sugbọn awọn obinrin nifẹ si ilana olomi gbona yi. ''Ilana yi maa n jẹ ki ẹjẹ jade daada.A maa jẹ ki ara bọ sipo pada kiakia.'' "Omi to lọwọrọ ati pepper soup lẹyin ibimọ maa n jẹ ki ile ọmọ sunki ti a si tun maa fọ ara abiyamọ'' Oogun lilo dara ṣa? Dokita Rosemary Ogu,onimọ itọju aboyun sọ pe o dara ki alaboyun gba imọran lọdọ awọn onimọ. O tun fero ọkan rẹ han lori bi awọn obinrin se le sesi ko kokoro aifojuri ti wọn ko ba seto itọju omi gbona daada. Ọjọgbọn Ogu ni : " Bi wọn ba lo omi gbona lẹyin ẹbi ni nkan bi ogun si ọgbọn isẹju ko buru sugbọn ko yẹ ki omi naa gbona ju.'' Lori wiwọ ikun abiyamọ o ni''A gba awọn obinrin ni imọran ki wọn jawọ nidi fifi omi gbona wọ ikun saaju ati lẹyin ibimọ,isesi ti ko dara to ni o si yẹ ki wọn jawọ nibẹ'' Onimọ yi tun gba awọn obinrin ni imọran lati ma se maa lọ si ọdọ awọn agbẹbi abẹle nitori ofin orileede Naijiria ko faaye gba wọn. "Nkan ti wọn n se lodi si ofin isẹ wọn si ti sokunfa iku ọpọ obinrin'' "Wọn kii se akọsẹmọsẹ bẹẹ wọn ko gbẹkọ nipa itọju alaboyun ni pataki bi nkan ba fẹ yiwọ'' | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-61287751 |
3politics
| Femi Fani-Kayode's defection: Ẹgbẹ́ OPC s'òkò ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí Femi | Ẹgbẹ Oodua Peoples Congress ti fi ẹsun kan Minisita irina ofurufu tẹlẹri, Femi Fani-Kayode pe ijọba gan ni o n ṣiṣẹ fun lasiko to n ṣe pẹlu awọn ajafẹtọ Yoruba Nation. Eyi jẹ jade ninu atẹjade ẹgb naa eyi ti akọwe ẹgbẹ Yinka Oguntimehin fọwọ si ninu eyi ti wọn ti sọ fun awọn araalu pe ki wọn tun maa reti awọn ọdalẹ mii pe awọn mii bi Fani-Kayode o le ṣai ma tun jade lati ẹkun Guusu-Iwọ Oorun. Wọn ṣapejuwe Fani-Kayode gẹgẹ "aṣiṣẹ f'oṣelu ti ko ni afojusun kankan" ati pe ko ni "ootọ inu kọbọ". Judasi ìran Oduduwa ni Femi Fani-Kayode pẹ̀lú bó ṣe darapọ̀ mọ́ APC- Sheikh Gumi Ojú ayé lásán ni Buhari ń ṣe, kò ní ifẹ́ ọmọ Nàìjíríà lọ́kàn - Fani-Kayode Ó pé mi kí n kú jù kí n darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC - Fani-Kayode Báńkì àpapọ̀ Nàìjíría ti pàsẹ títi ojú òpó Aboki FX pa Ẹ san N20bn náà fún Igboho kíákíá; Dáa padà! Ìjọba àpapọ̀ jùú sí ẹgbẹ́ Ilana Ọmọ Oodua Ẹgbẹ naa ni ko ya awọn lẹnu rara pe Femi lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC toripe oun atawọn eekan ẹgbẹ naa ti n fara yira kaakiri orilẹede. Ṣaaju ko to lọ darapọ mọ APC, FFK jẹ ọkan lara awọn oloṣelu to n fọn rere ajijafẹtọ Yoruba Nation, Sunday Adeyemo ti ọpọ maa n pe ni Igboho. Bakan naa, Igboho ti sọọ ri ninu atẹ́jade rẹ ti agbẹnusọ rẹ tẹlẹ, Olayomi Koiki fi sita ninu oṣu kẹta ọdun 2021 pe "Alẹnulọrọ pataki ni Oloye Femi Fani-Kayode to n ti awọn lẹyin ninu ija fun orilẹede Yoruba Nation. A ni gbogbo idaniloju ninu rẹ (Fani-Kayode)". Ẹgbẹ OPC wa rọ awọn ọmọ Yoruba pe ki wọn ma roo pe ijanikulẹ ni ohun ti Minisita tẹlẹri ṣe toripe "bii ọga lawọn oloṣelu Naijiria ti wọn maa n pa awọ da ni gbogbo igba". Kí ẹnikẹ́ni má gbé ìyá mi síta mọ́, mí o ní agbẹnusọ kankan mọ́- Sunday Igboho | Femi Fani-Kayode's defection: Ẹgbẹ́ OPC s'òkò ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí Femi Ẹgbẹ Oodua Peoples Congress ti fi ẹsun kan Minisita irina ofurufu tẹlẹri, Femi Fani-Kayode pe ijọba gan ni o n ṣiṣẹ fun lasiko to n ṣe pẹlu awọn ajafẹtọ Yoruba Nation. Eyi jẹ jade ninu atẹjade ẹgb naa eyi ti akọwe ẹgbẹ Yinka Oguntimehin fọwọ si ninu eyi ti wọn ti sọ fun awọn araalu pe ki wọn tun maa reti awọn ọdalẹ mii pe awọn mii bi Fani-Kayode o le ṣai ma tun jade lati ẹkun Guusu-Iwọ Oorun. Wọn ṣapejuwe Fani-Kayode gẹgẹ "aṣiṣẹ f'oṣelu ti ko ni afojusun kankan" ati pe ko ni "ootọ inu kọbọ". Judasi ìran Oduduwa ni Femi Fani-Kayode pẹ̀lú bó ṣe darapọ̀ mọ́ APC- Sheikh Gumi Ojú ayé lásán ni Buhari ń ṣe, kò ní ifẹ́ ọmọ Nàìjíríà lọ́kàn - Fani-Kayode Ó pé mi kí n kú jù kí n darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC - Fani-Kayode Báńkì àpapọ̀ Nàìjíría ti pàsẹ títi ojú òpó Aboki FX pa Ẹ san N20bn náà fún Igboho kíákíá; Dáa padà! Ìjọba àpapọ̀ jùú sí ẹgbẹ́ Ilana Ọmọ Oodua Ẹgbẹ naa ni ko ya awọn lẹnu rara pe Femi lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC toripe oun atawọn eekan ẹgbẹ naa ti n fara yira kaakiri orilẹede. Ṣaaju ko to lọ darapọ mọ APC, FFK jẹ ọkan lara awọn oloṣelu to n fọn rere ajijafẹtọ Yoruba Nation, Sunday Adeyemo ti ọpọ maa n pe ni Igboho. Bakan naa, Igboho ti sọọ ri ninu atẹ́jade rẹ ti agbẹnusọ rẹ tẹlẹ, Olayomi Koiki fi sita ninu oṣu kẹta ọdun 2021 pe "Alẹnulọrọ pataki ni Oloye Femi Fani-Kayode to n ti awọn lẹyin ninu ija fun orilẹede Yoruba Nation. A ni gbogbo idaniloju ninu rẹ (Fani-Kayode)". Ẹgbẹ OPC wa rọ awọn ọmọ Yoruba pe ki wọn ma roo pe ijanikulẹ ni ohun ti Minisita tẹlẹri ṣe toripe "bii ọga lawọn oloṣelu Naijiria ti wọn maa n pa awọ da ni gbogbo igba". Kí ẹnikẹ́ni má gbé ìyá mi síta mọ́, mí o ní agbẹnusọ kankan mọ́- Sunday Igboho | https://www.bbc.com/yoruba/58602287 |
5sports
| Manchester City vs Manchester United: Man United fọ́ Man City lẹ́nu yánkanyànkan mọ́lé | Igba la a ni ẹnikan ko le lo ile aye gbo, bayii lọrọ ri fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ti ife ẹyẹ idije Premier League wa lọwọ wọn. Orogun wọn ti wọn jọ wa niluu kan naa, Manchester United lo fiya ajẹtun iya jẹwọn lairo tẹlẹ nile wọn. Marcus Rashford lo gbayo alakọkọ wọle fun Man United nigba ti ẹrọ VAR fun wọn ni pẹnariti. Ere bọọlu mọ Man City loju nigba ti Anthony Martial gba goolu keji sawọn Man City, lo ba ayo meji sodo ti wọn fi n siwaju wọn. Nicolas Otamendi dayo kan pada, amọ ẹpa ko boro mọ fun Man City. Esi ifẹsẹwọnsẹ yii jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu nitori ko si ẹni to le pe Man U le na Man City mọ le. Àkọ́já ewé akọ́nimọ̀ọ́gbá fìdíhẹẹ́ Everton, ìyà ló bádé fún Chelsea Ilẹ n yọ gbe Chelsea ṣubu yakata ni Goodison Park ti ṣe papa iṣere Everton Ẹgbẹ agbabọọlu Everton ṣẹṣẹ le akọnimọọgba wọn Marco Silva lọ ni, ki wọn to yan Duncan Ferguson gẹgẹ bi akọnimọọgba fidihẹ. Iyalẹnu lo jẹ pe iṣẹju marun un ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa ni Richarlison gbayo kan wọle Chelsea lairo tẹlẹ. Ka to wi, ka to fọ, Dominic Calvert-Lewin gbayo keji sawọn Chelsea lẹyin iṣẹju mẹrin ti ipele keji ere bọọlu naa bẹrẹ. Mateo Kovacic dayo kan pada fun Chelsea, amọ Calvert-Lewin gbayo kẹta wọle fun Everton, ni okote ba bo niru fun Chelsea. Lẹyin ọ rẹyin, ami ayo mẹta sẹyọkan ni Everton fi gbo ewuro soju Chelsea | Manchester City vs Manchester United: Man United fọ́ Man City lẹ́nu yánkanyànkan mọ́lé Igba la a ni ẹnikan ko le lo ile aye gbo, bayii lọrọ ri fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ti ife ẹyẹ idije Premier League wa lọwọ wọn. Orogun wọn ti wọn jọ wa niluu kan naa, Manchester United lo fiya ajẹtun iya jẹwọn lairo tẹlẹ nile wọn. Marcus Rashford lo gbayo alakọkọ wọle fun Man United nigba ti ẹrọ VAR fun wọn ni pẹnariti. Ere bọọlu mọ Man City loju nigba ti Anthony Martial gba goolu keji sawọn Man City, lo ba ayo meji sodo ti wọn fi n siwaju wọn. Nicolas Otamendi dayo kan pada, amọ ẹpa ko boro mọ fun Man City. Esi ifẹsẹwọnsẹ yii jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu nitori ko si ẹni to le pe Man U le na Man City mọ le. Àkọ́já ewé akọ́nimọ̀ọ́gbá fìdíhẹẹ́ Everton, ìyà ló bádé fún Chelsea Ilẹ n yọ gbe Chelsea ṣubu yakata ni Goodison Park ti ṣe papa iṣere Everton Ẹgbẹ agbabọọlu Everton ṣẹṣẹ le akọnimọọgba wọn Marco Silva lọ ni, ki wọn to yan Duncan Ferguson gẹgẹ bi akọnimọọgba fidihẹ. Iyalẹnu lo jẹ pe iṣẹju marun un ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa ni Richarlison gbayo kan wọle Chelsea lairo tẹlẹ. Ka to wi, ka to fọ, Dominic Calvert-Lewin gbayo keji sawọn Chelsea lẹyin iṣẹju mẹrin ti ipele keji ere bọọlu naa bẹrẹ. Mateo Kovacic dayo kan pada fun Chelsea, amọ Calvert-Lewin gbayo kẹta wọle fun Everton, ni okote ba bo niru fun Chelsea. Lẹyin ọ rẹyin, ami ayo mẹta sẹyọkan ni Everton fi gbo ewuro soju Chelsea | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-50700314 |
1entertainment
| Baba Suwe: Àkọ́bí Omidina ní òun fẹ́ràn láti máa ń wo bàbá òun lórí Tẹlifísàn ni kékeré láì mọ̀ pé bàbá òun ni | Obinrin miran tun ti jade pe oun ni oun bi akọbi ọmọ fun Baba Suwe, ti ọmọ oun si jẹ akọbi ọkunrin. Orukọ obinrin naa ni Adenike Muibat Omidina, ti o si ni orukọ akọbi ọmọ Baba Suwe ti oun bi fun ni Omobowale. Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lọjọ isinku Baba Suwe, Adenike ni ọmọ oun ko ti ba baba rẹ rin pupọ ko to di pe o jade laye. Amọ o ni ọmọ oun nifẹ lati maa wo iran baba rẹ lori tẹlifisan amọ o dun awọn pe asiko ti ọmọ oun ko ba gbadun Baba Suwe bi baba rẹ, ni adẹrinposonu naa dagbere faye. "O dun mi pupọ pe Baba Suwe ku ni akoko yii mo si wa n gba awọn ọmọ rẹ nimọran pe ki wọn se ara wọn ni ọkan nitori baba kan soso lo bi wọn. Kí ló yẹ kóo sáré ṣe bí ejò bá ṣá ọ jẹ? Wo ọ̀ná tí àwọn okùnrin lè gbà ṣe ìfètòsọ́mọbíbí láì lo kọ́ndọ́ọ̀mù lásìkò ìbálòpọ̀ Wọn ko gbọdọ gba esu laaye ninu irinajo aye wọn, ki wọn le gbe orukọ baba wọn ga siwaju si nibi to se isẹ rere de." Adenike Omidina wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ Baba Suwe si afẹfẹ rere, ko si ma se iku rẹ ni akufa laarin ẹbi. Mo fẹran lati maa wo Baba Suwe lori tẹlifisan lai mọ pe baba mi ni: Nigba toun naa n sọrọ nipa baba rẹ, akọbi Baba Suwe Akanbi Sherriff Omobowale Omidina ni oun kan maa n wo Baba Suwe lori mohunmaworan ni lai mọ pe baba oun ni. O ni oun nifẹ rẹ pupọ, amọ igbakuugba ti oun ba n wo ere Baba Suwe ni iya oun yoo ni ki oun gbe oju opo naa kuro loju mahunmaworan lọ si ibomiran. O fikun pe nigba ti oun tun lọ si oke okun, oun tun gbọ okiki Baba Suwe sugbọn isẹ ko jẹ ki oun ni akoko lati maa wo, bi oun se maa n wo tẹlẹ. "Isẹ agbẹmila ati olutọju alaisan ni mo n se, ti wọn ba ti gbe alaisan wa, n ki ni anfaani lati le wo Baba Suwe bo se yẹ. Amọ mo ri baba mi ko to ku. Mo wa si Naijiria bii ẹẹmẹta amọ mo ri wọn bii ẹẹmeji. Inu mi dun pe mo se nnkan fun wọn, ki wọn to ku, tori ẹmi yẹn kan sọ si mi lọkan pe ki n ra nnkan ijoko fun wọn. Ẹni to ba ra nnkan ijoko fun eeyan, ti fun onitọun ni isinmi, bi mo ba tiẹ ni wahala pẹlu wọn tẹlẹ, nnkan ti mo se yẹn gan yoo jẹ ki inu wọn yọ. Inu mi si dun pe mo bu yeepẹ si wọn lori, ti ki si se ẹyin ti wọn ku tan ni mo mọ wọn." Akọbi Baba Suwe wa rọ awọn ẹbi lati mase se ounkohun ti yoo ba ẹyin baba oun jẹ, ki gbogbo ọmọ si se ohun to yẹ lati gbe orukọ rẹ ga si lẹyin iku rẹ. | Baba Suwe: Àkọ́bí Omidina ní òun fẹ́ràn láti máa ń wo bàbá òun lórí Tẹlifísàn ni kékeré láì mọ̀ pé bàbá òun ni Obinrin miran tun ti jade pe oun ni oun bi akọbi ọmọ fun Baba Suwe, ti ọmọ oun si jẹ akọbi ọkunrin. Orukọ obinrin naa ni Adenike Muibat Omidina, ti o si ni orukọ akọbi ọmọ Baba Suwe ti oun bi fun ni Omobowale. Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lọjọ isinku Baba Suwe, Adenike ni ọmọ oun ko ti ba baba rẹ rin pupọ ko to di pe o jade laye. Amọ o ni ọmọ oun nifẹ lati maa wo iran baba rẹ lori tẹlifisan amọ o dun awọn pe asiko ti ọmọ oun ko ba gbadun Baba Suwe bi baba rẹ, ni adẹrinposonu naa dagbere faye. "O dun mi pupọ pe Baba Suwe ku ni akoko yii mo si wa n gba awọn ọmọ rẹ nimọran pe ki wọn se ara wọn ni ọkan nitori baba kan soso lo bi wọn. Kí ló yẹ kóo sáré ṣe bí ejò bá ṣá ọ jẹ? Wo ọ̀ná tí àwọn okùnrin lè gbà ṣe ìfètòsọ́mọbíbí láì lo kọ́ndọ́ọ̀mù lásìkò ìbálòpọ̀ Wọn ko gbọdọ gba esu laaye ninu irinajo aye wọn, ki wọn le gbe orukọ baba wọn ga siwaju si nibi to se isẹ rere de." Adenike Omidina wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ Baba Suwe si afẹfẹ rere, ko si ma se iku rẹ ni akufa laarin ẹbi. Mo fẹran lati maa wo Baba Suwe lori tẹlifisan lai mọ pe baba mi ni: Nigba toun naa n sọrọ nipa baba rẹ, akọbi Baba Suwe Akanbi Sherriff Omobowale Omidina ni oun kan maa n wo Baba Suwe lori mohunmaworan ni lai mọ pe baba oun ni. O ni oun nifẹ rẹ pupọ, amọ igbakuugba ti oun ba n wo ere Baba Suwe ni iya oun yoo ni ki oun gbe oju opo naa kuro loju mahunmaworan lọ si ibomiran. O fikun pe nigba ti oun tun lọ si oke okun, oun tun gbọ okiki Baba Suwe sugbọn isẹ ko jẹ ki oun ni akoko lati maa wo, bi oun se maa n wo tẹlẹ. "Isẹ agbẹmila ati olutọju alaisan ni mo n se, ti wọn ba ti gbe alaisan wa, n ki ni anfaani lati le wo Baba Suwe bo se yẹ. Amọ mo ri baba mi ko to ku. Mo wa si Naijiria bii ẹẹmẹta amọ mo ri wọn bii ẹẹmeji. Inu mi dun pe mo se nnkan fun wọn, ki wọn to ku, tori ẹmi yẹn kan sọ si mi lọkan pe ki n ra nnkan ijoko fun wọn. Ẹni to ba ra nnkan ijoko fun eeyan, ti fun onitọun ni isinmi, bi mo ba tiẹ ni wahala pẹlu wọn tẹlẹ, nnkan ti mo se yẹn gan yoo jẹ ki inu wọn yọ. Inu mi si dun pe mo bu yeepẹ si wọn lori, ti ki si se ẹyin ti wọn ku tan ni mo mọ wọn." Akọbi Baba Suwe wa rọ awọn ẹbi lati mase se ounkohun ti yoo ba ẹyin baba oun jẹ, ki gbogbo ọmọ si se ohun to yẹ lati gbe orukọ rẹ ga si lẹyin iku rẹ. | https://www.bbc.com/yoruba/afrika-59441963 |
1entertainment
| Actors who remarried: Àwọn òṣèré sinimá tí wọ́n ti rìnrìnàjò ìfẹ́ lẹ́ẹ̀méjì | Ọrọ ifẹ lagbara kaakiri agbaye larin obinrin ati ọkunrin ti wọn ti balaga. Lẹyin ti ọrọ ifẹ ti wọ tan ti ọkunrin gbe obinrin ni iyawo, Oriṣi nkan lo maa n fa gbọnmisii omi ko too laarin ololufẹ meji ni eyi ti ko yọ awọn oṣere Naijiria naa silẹ. Oriṣirisi nnkan lo maa n ṣẹlẹ lagbo awọn oṣere, bii ayẹyẹ iṣile, mọto rira, ija laarin ara wọn ati kikọra ẹni silẹ. Kikọ ara ẹni silẹ yii naa maa n waye laarin awọn oṣere tiata nilẹ yii ati ggẹ bo ṣe jẹ pe ko si ẹni ti iwa rẹ pe tan lagbaye. Bi o tilẹ jẹ ọpọlọpọ nnkan lo maa n fa ikọra ẹni yii, ti aṣiri rẹ ko han si awọn ololufẹ elere agbelewo lọpọ igba. Awọn oṣere yii naa ṣeeṣe ki wọn ṣalai gbadun irinajo ifẹ wọn ni igba akọkọ, ko jẹ pe ti wọn ba pade ẹlomii lẹẹkeji ni ọkan wọn ṣẹṣẹ maa balẹ sii. Eyi to fihan pe, ko si igba ti eeyan ko le ri ayọ rẹ he ninu irin ajo ifẹ rẹ. Diẹ lara awọn oṣere sinima Nollywood ti igbeyawo wọn tuka ti wọn si ṣe igbeyawo lẹẹkeji ki wọn to ri ayọ ni yii: 1. Funke Akindele: Funke Akindele ti di agba ọjẹ ninu ere agbelewo. Awọn ere bii Jenifa, Ekurọ, Aye olomo kan ati bẹẹ bẹẹ lọ ṣafihan Funke lẹnu iṣẹ oojọ rẹ. Ni ibẹrẹ pẹpẹ ni Funke kọ fẹ Almaroof Oloyede lọdun 2012, sugbọn tirela gba aarin wọn kọja loṣu keje, ọdun 2013 ti awọn mejeeji si fi ọrọ lede pe igbeyawọ naa ti tu ka. Ìdúnnú ṣubú layọ̀ fún Funke Akindele àti ọkọ rẹ, ìjọba Eko fún wọn ní ìdáríjì Omo Ghetto: Funke Akindele ṣàlàyé bí àwọn agbébọn ṣe kọlù wọn làsíkò tí wọ́n ń ya fíìmù Laipe sii ni Eledua tun da Funke lohun ti Abdulrasheed Bello, ti apele rẹ n jẹ JJC gbe e niyawo ni igba to ku diẹ ko pe ọmọ ọdun mọkandinlogoji ni ilu London. Bayii Olorun ti fi ibeji ta Funke Akindele Bello lọrẹ Funke Akindele ti di ìyábejì pẹlu JJC to ti ni awọn ọmọ tẹlẹ ko to pade Funke Akindele. 2. Toyin Abraham: O ṣeeṣe ko jẹ wipe Toyin Aimakhu tabi Toyin Abraham lẹ mo orukọ rẹ si amọ sibẹ sibẹ odu ni Toyin kii ṣe aimọ fun oloko lagbo oṣere fiimu ni Naijiria. Toyin kọkọ n fẹ akẹgbẹ rẹ Adeniyi Johnson lọdun 2013 ti ifẹ naa si n farahan bi eyi to larinrin lori ayelujara tori awọn mejeji kii kọ lati gbe ọrọ ifẹ ara wọn sita. Ẹ má pa ara yín lórí ọ̀rọ̀ mi - Kolawole Ajewole ọkọ Toyin Abraham fohùn léde Nkechi Blessing vs Toyin Abraham: Nkechi tí tọrọ ìdáríjí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ akẹgbẹ́ rẹ̀, Toyin Abraham Kí ló fa ìjà rọ̀fọ̀rọ́fọ̀ láàrin Toyin Abraham àti olólùfẹ́ rẹ̀ lórí ayélujára? Iyalẹnu lo jẹ fawọn ololufẹ wọn ninu dun 2015 ti iroyin gbode kan pe tirela ti gba aarin awọn ilumọọka ololufẹ meji yii ti awọn naa si kede ituka wọn. Ẹwẹ, iroyin mii to tun ti n jẹ ki awọn ololufẹ wọn maa jaye ori wọn lọ ni wipe awọn oṣere mejeeji yii ti ṣegbeyawo pẹlu awọn miiran ti igbeyawo wọn si n tẹsiwaju. Iyawo Adeniyi Johnson kii ṣe oṣere rara amọ ọkọ ti Toyin Abraham fẹ ni tirẹ jẹ akẹgbẹ rẹ, Kolawole Ajeyemi ti ọmọ si ti wa laarin awọn mejeji bayii ti gbogbo aye fi n pe wọn ni "Mummy ati Daddy Ire". 3. Foluke Daramola: Arẹwa ati gbajumọ osẹre naa ni Folukẹ Daramọla to ti gbe ọpọlọpọ sinima Yoruba agbelewo sita. O fẹ Tunde Sobowale lọdun 2005, sugbọn igeyawo naa tuka ni igba to di ọdun 2008. Nigba to ba awọn oniroyin sọrọ lọdun to kọja, Foluke ni ohun to ba oun ninu jẹ ju lọ ni igba ti igeyawo oun akọkọ fori sọgi. Sugbọn ni bayii, idunnu ati ayo loun fi n gbe nile ọkọ rẹ tuntun. Folukẹ Daramola Salakọ gbagbọ pe o san ki ikọsilẹ waye ninu igbeyawo ju ki ẹni kan lọ pa ara rẹ danu tabi ki o maa foriti igbeyawo ti iwa ipá wa ninu rẹ lọ. 4. Mercy Aigbe: Mercy Aigbe naa jẹ gbajugbaja laarin awọn oṣerebinrin fiimu Yoruba ti oniruuru iroyin si tijade nipa igbeyawo rẹ laipẹ Latẹyinwa naa, oniruuru ni iroyin to ti jade nipa igbeyawo rẹ lara eyi ti ọkan ninu wọn sọ pe aya arakunrin ẹya Igbo kan ni Ercy Aigbe ti kọkọ jẹ ti wọn si ni o bi ọmọbinrin kan fun un. Amọ a gbọ pe ko pẹ ti igbeyawo naa lana laarin ọdun diẹ. Lọdun 2013, Mercy ati ọgbẹni Lanre Gentry ni Kootu Ikoyi ni Eko. Ka to wi ka to fọ, igbeyawo naa foriṣopan. Father's Day fa gbas-gbos láàrin Mercy Aigbe àti ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Gentry, ọkọ́ ní òun le tú àwọn àṣírí ìwà nọ̀bì rẹ̀ síta Ninu ọdun yii ni Mercy Aigbe to ti maa n pe ara rẹ ni Aya D'owner ti pada fẹ D'owner ọhun ti ọpọ eeyan mọ̀ si Adekaz. Bo tilẹ jẹ ọrọ naa ru nkan bi ija jade laarin awọn ti ọrọ kan, iyẹn Mercy, Adekaz ati iyawo rẹ tẹlẹ, Mercy ti ṣe bi ni kọ eti ọgbọin si gbogbo ọrọ to n jade. Wo ohun táwọn èèyàn ń sọ sí Mercy Aigbe torí àṣírí tí ìyàwó àkọ́fẹ́ Adekaz tú síta 5. Bukky Wright: Orukọ ọkọ akọkọ Bukky ni Gbeyega Amu, ti Ọlọrun si fi ọmọ meji ta wọn lọrẹ. Sugbọn fun idi kan tabi omiran, igbeyawo naa tuka, lẹyin naa ni Bukky bẹrẹ ere ifẹ pelu Rotimi Makinde, to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣoju lọwọlọwọ. Lai pẹ si asiko yii ni awọn kan tun gbe iroyin kan kiri lori ayelujara pe Bukky n fẹ gbajugbaja akọroyin ni, Femi Davies. Sugbọn ẹmi ere ifẹ naa ko gun pupọ ni bi Bukky ṣe tẹsiwaju igbe aye rẹ. Lẹyin naa lo tun fẹ Bolaji Saheed to jẹ ọkọ rẹ kẹrin, sugbọn tirela tun gba aarin wọn kọja. Lẹyin Saheed ni oṣere naa fẹ ọkọ rẹ ẹlẹẹkarun un, Adewale Onitiri to n fi ilẹ Amẹrika ṣebugbe, sugbọn o ṣeni laanu pe, iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe ko si ẹni to le sọ ni pato ohun to n ṣẹlẹ bayii. 6. Stella Damascus: Ọkọ akọkọ to fẹ Stella to di oloogbe lọjọ kẹta, oṣu kejila, ọdun 2004 lo mu ko fẹ Emeka Nzeribe ni bonkẹlẹ lọdun 2007, sugbọn igbeyawo naa ko pẹ pupọ. Lọwọ yii, Daniel Ademinokan ni ọkọ rẹ, ẹni to jẹ ọkọ Doris Simeon tẹlẹri. Doris Simeon jẹ gbajugbaja oṣere ti oun ati Ademinokan bi ọmọkunrin kan fun ara wọn. Stella ti ko lọ si Amerika bayii pẹlu Daniel Ademinokan. Awọn mejeeji n tẹsiwaju ninu igbeyawo wọn lorilẹ-ede Amẹrika. 7. Clarion Chukwurah: Wọ ki ilu mọ ni Clarion ninu iṣe osere lede oyinbo lorilẹ-ede Naijiria. Lọdun 2003 ni igbeyawo rẹ pẹlu Tunde Abiola to fori sogi si iyalẹnu ọpọ awọn ololufẹ. O tẹsiwaju lati fẹ Femi Oduneye ti awọn eeyan mọ si Femi Egyptian lọjọ ayajọ Valentine lọdun 2004, sugbọn igeyawo naa tun fori sogi loṣu karun un, ọdun 2006. Nigba to di ọdun 2016 ni Clarion taa tan pẹlu ololufẹ rẹ, Anthony Boyd to n fi ile Amẹrika ṣebugbe. 8. Anne Njemanze: Arewa Anne Njemanze lo fẹ gbajugbaja oṣere ni ede oyinbo ati Yoruba lẹẹkọọkan ni, Segun Arinze. Lẹyin ti wọn bi ọmọ obinrin kan fun ara wọn ni igbeyawo naa tuka. Omo obinrin naa ti Anne bi fun Arinze ti di sisi ọmọ ọdun metadinlogun bayii. Lẹyin eyi ni Anne lọ fẹ Silver Ojieson ṣugbọn wọn kọ ara wọn silẹ latari iwa ipa to n ṣẹlẹ ninu idile wọn. 9. Shan George Nigba ti oṣere yii wa lọmọ ọdun mẹrindinlogun lọdun 1985 ni wọn ti kọ gbe e niyawo to si bi ọmọ meji fun ọkọ rẹ nigba naa. Ni igba to di ọdun 1991 ti George pe ọmọ ọdun mọkanlelogun ni wọn kọ ara wọn silẹ. Awọn kan gbe iroyin boya ahesọ pe Shan tun fẹ ọkọ miran sugbọn igbeyawo ọhun ko yọri si rere. Lẹyin eyii ni Shan George fẹ Anthony Nwosisi to jẹ ọkọ rẹ kẹta, sugbọn igbeyawo ọhun ko pẹ to fi tuka bakan naa. | Actors who remarried: Àwọn òṣèré sinimá tí wọ́n ti rìnrìnàjò ìfẹ́ lẹ́ẹ̀méjì Ọrọ ifẹ lagbara kaakiri agbaye larin obinrin ati ọkunrin ti wọn ti balaga. Lẹyin ti ọrọ ifẹ ti wọ tan ti ọkunrin gbe obinrin ni iyawo, Oriṣi nkan lo maa n fa gbọnmisii omi ko too laarin ololufẹ meji ni eyi ti ko yọ awọn oṣere Naijiria naa silẹ. Oriṣirisi nnkan lo maa n ṣẹlẹ lagbo awọn oṣere, bii ayẹyẹ iṣile, mọto rira, ija laarin ara wọn ati kikọra ẹni silẹ. Kikọ ara ẹni silẹ yii naa maa n waye laarin awọn oṣere tiata nilẹ yii ati ggẹ bo ṣe jẹ pe ko si ẹni ti iwa rẹ pe tan lagbaye. Bi o tilẹ jẹ ọpọlọpọ nnkan lo maa n fa ikọra ẹni yii, ti aṣiri rẹ ko han si awọn ololufẹ elere agbelewo lọpọ igba. Awọn oṣere yii naa ṣeeṣe ki wọn ṣalai gbadun irinajo ifẹ wọn ni igba akọkọ, ko jẹ pe ti wọn ba pade ẹlomii lẹẹkeji ni ọkan wọn ṣẹṣẹ maa balẹ sii. Eyi to fihan pe, ko si igba ti eeyan ko le ri ayọ rẹ he ninu irin ajo ifẹ rẹ. Diẹ lara awọn oṣere sinima Nollywood ti igbeyawo wọn tuka ti wọn si ṣe igbeyawo lẹẹkeji ki wọn to ri ayọ ni yii: 1. Funke Akindele: Funke Akindele ti di agba ọjẹ ninu ere agbelewo. Awọn ere bii Jenifa, Ekurọ, Aye olomo kan ati bẹẹ bẹẹ lọ ṣafihan Funke lẹnu iṣẹ oojọ rẹ. Ni ibẹrẹ pẹpẹ ni Funke kọ fẹ Almaroof Oloyede lọdun 2012, sugbọn tirela gba aarin wọn kọja loṣu keje, ọdun 2013 ti awọn mejeeji si fi ọrọ lede pe igbeyawọ naa ti tu ka. Ìdúnnú ṣubú layọ̀ fún Funke Akindele àti ọkọ rẹ, ìjọba Eko fún wọn ní ìdáríjì Omo Ghetto: Funke Akindele ṣàlàyé bí àwọn agbébọn ṣe kọlù wọn làsíkò tí wọ́n ń ya fíìmù Laipe sii ni Eledua tun da Funke lohun ti Abdulrasheed Bello, ti apele rẹ n jẹ JJC gbe e niyawo ni igba to ku diẹ ko pe ọmọ ọdun mọkandinlogoji ni ilu London. Bayii Olorun ti fi ibeji ta Funke Akindele Bello lọrẹ Funke Akindele ti di ìyábejì pẹlu JJC to ti ni awọn ọmọ tẹlẹ ko to pade Funke Akindele. 2. Toyin Abraham: O ṣeeṣe ko jẹ wipe Toyin Aimakhu tabi Toyin Abraham lẹ mo orukọ rẹ si amọ sibẹ sibẹ odu ni Toyin kii ṣe aimọ fun oloko lagbo oṣere fiimu ni Naijiria. Toyin kọkọ n fẹ akẹgbẹ rẹ Adeniyi Johnson lọdun 2013 ti ifẹ naa si n farahan bi eyi to larinrin lori ayelujara tori awọn mejeji kii kọ lati gbe ọrọ ifẹ ara wọn sita. Ẹ má pa ara yín lórí ọ̀rọ̀ mi - Kolawole Ajewole ọkọ Toyin Abraham fohùn léde Nkechi Blessing vs Toyin Abraham: Nkechi tí tọrọ ìdáríjí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ akẹgbẹ́ rẹ̀, Toyin Abraham Kí ló fa ìjà rọ̀fọ̀rọ́fọ̀ láàrin Toyin Abraham àti olólùfẹ́ rẹ̀ lórí ayélujára? Iyalẹnu lo jẹ fawọn ololufẹ wọn ninu dun 2015 ti iroyin gbode kan pe tirela ti gba aarin awọn ilumọọka ololufẹ meji yii ti awọn naa si kede ituka wọn. Ẹwẹ, iroyin mii to tun ti n jẹ ki awọn ololufẹ wọn maa jaye ori wọn lọ ni wipe awọn oṣere mejeeji yii ti ṣegbeyawo pẹlu awọn miiran ti igbeyawo wọn si n tẹsiwaju. Iyawo Adeniyi Johnson kii ṣe oṣere rara amọ ọkọ ti Toyin Abraham fẹ ni tirẹ jẹ akẹgbẹ rẹ, Kolawole Ajeyemi ti ọmọ si ti wa laarin awọn mejeji bayii ti gbogbo aye fi n pe wọn ni "Mummy ati Daddy Ire". 3. Foluke Daramola: Arẹwa ati gbajumọ osẹre naa ni Folukẹ Daramọla to ti gbe ọpọlọpọ sinima Yoruba agbelewo sita. O fẹ Tunde Sobowale lọdun 2005, sugbọn igeyawo naa tuka ni igba to di ọdun 2008. Nigba to ba awọn oniroyin sọrọ lọdun to kọja, Foluke ni ohun to ba oun ninu jẹ ju lọ ni igba ti igeyawo oun akọkọ fori sọgi. Sugbọn ni bayii, idunnu ati ayo loun fi n gbe nile ọkọ rẹ tuntun. Folukẹ Daramola Salakọ gbagbọ pe o san ki ikọsilẹ waye ninu igbeyawo ju ki ẹni kan lọ pa ara rẹ danu tabi ki o maa foriti igbeyawo ti iwa ipá wa ninu rẹ lọ. 4. Mercy Aigbe: Mercy Aigbe naa jẹ gbajugbaja laarin awọn oṣerebinrin fiimu Yoruba ti oniruuru iroyin si tijade nipa igbeyawo rẹ laipẹ Latẹyinwa naa, oniruuru ni iroyin to ti jade nipa igbeyawo rẹ lara eyi ti ọkan ninu wọn sọ pe aya arakunrin ẹya Igbo kan ni Ercy Aigbe ti kọkọ jẹ ti wọn si ni o bi ọmọbinrin kan fun un. Amọ a gbọ pe ko pẹ ti igbeyawo naa lana laarin ọdun diẹ. Lọdun 2013, Mercy ati ọgbẹni Lanre Gentry ni Kootu Ikoyi ni Eko. Ka to wi ka to fọ, igbeyawo naa foriṣopan. Father's Day fa gbas-gbos láàrin Mercy Aigbe àti ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Gentry, ọkọ́ ní òun le tú àwọn àṣírí ìwà nọ̀bì rẹ̀ síta Ninu ọdun yii ni Mercy Aigbe to ti maa n pe ara rẹ ni Aya D'owner ti pada fẹ D'owner ọhun ti ọpọ eeyan mọ̀ si Adekaz. Bo tilẹ jẹ ọrọ naa ru nkan bi ija jade laarin awọn ti ọrọ kan, iyẹn Mercy, Adekaz ati iyawo rẹ tẹlẹ, Mercy ti ṣe bi ni kọ eti ọgbọin si gbogbo ọrọ to n jade. Wo ohun táwọn èèyàn ń sọ sí Mercy Aigbe torí àṣírí tí ìyàwó àkọ́fẹ́ Adekaz tú síta 5. Bukky Wright: Orukọ ọkọ akọkọ Bukky ni Gbeyega Amu, ti Ọlọrun si fi ọmọ meji ta wọn lọrẹ. Sugbọn fun idi kan tabi omiran, igbeyawo naa tuka, lẹyin naa ni Bukky bẹrẹ ere ifẹ pelu Rotimi Makinde, to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣoju lọwọlọwọ. Lai pẹ si asiko yii ni awọn kan tun gbe iroyin kan kiri lori ayelujara pe Bukky n fẹ gbajugbaja akọroyin ni, Femi Davies. Sugbọn ẹmi ere ifẹ naa ko gun pupọ ni bi Bukky ṣe tẹsiwaju igbe aye rẹ. Lẹyin naa lo tun fẹ Bolaji Saheed to jẹ ọkọ rẹ kẹrin, sugbọn tirela tun gba aarin wọn kọja. Lẹyin Saheed ni oṣere naa fẹ ọkọ rẹ ẹlẹẹkarun un, Adewale Onitiri to n fi ilẹ Amẹrika ṣebugbe, sugbọn o ṣeni laanu pe, iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe ko si ẹni to le sọ ni pato ohun to n ṣẹlẹ bayii. 6. Stella Damascus: Ọkọ akọkọ to fẹ Stella to di oloogbe lọjọ kẹta, oṣu kejila, ọdun 2004 lo mu ko fẹ Emeka Nzeribe ni bonkẹlẹ lọdun 2007, sugbọn igbeyawo naa ko pẹ pupọ. Lọwọ yii, Daniel Ademinokan ni ọkọ rẹ, ẹni to jẹ ọkọ Doris Simeon tẹlẹri. Doris Simeon jẹ gbajugbaja oṣere ti oun ati Ademinokan bi ọmọkunrin kan fun ara wọn. Stella ti ko lọ si Amerika bayii pẹlu Daniel Ademinokan. Awọn mejeeji n tẹsiwaju ninu igbeyawo wọn lorilẹ-ede Amẹrika. 7. Clarion Chukwurah: Wọ ki ilu mọ ni Clarion ninu iṣe osere lede oyinbo lorilẹ-ede Naijiria. Lọdun 2003 ni igbeyawo rẹ pẹlu Tunde Abiola to fori sogi si iyalẹnu ọpọ awọn ololufẹ. O tẹsiwaju lati fẹ Femi Oduneye ti awọn eeyan mọ si Femi Egyptian lọjọ ayajọ Valentine lọdun 2004, sugbọn igeyawo naa tun fori sogi loṣu karun un, ọdun 2006. Nigba to di ọdun 2016 ni Clarion taa tan pẹlu ololufẹ rẹ, Anthony Boyd to n fi ile Amẹrika ṣebugbe. 8. Anne Njemanze: Arewa Anne Njemanze lo fẹ gbajugbaja oṣere ni ede oyinbo ati Yoruba lẹẹkọọkan ni, Segun Arinze. Lẹyin ti wọn bi ọmọ obinrin kan fun ara wọn ni igbeyawo naa tuka. Omo obinrin naa ti Anne bi fun Arinze ti di sisi ọmọ ọdun metadinlogun bayii. Lẹyin eyi ni Anne lọ fẹ Silver Ojieson ṣugbọn wọn kọ ara wọn silẹ latari iwa ipa to n ṣẹlẹ ninu idile wọn. 9. Shan George Nigba ti oṣere yii wa lọmọ ọdun mẹrindinlogun lọdun 1985 ni wọn ti kọ gbe e niyawo to si bi ọmọ meji fun ọkọ rẹ nigba naa. Ni igba to di ọdun 1991 ti George pe ọmọ ọdun mọkanlelogun ni wọn kọ ara wọn silẹ. Awọn kan gbe iroyin boya ahesọ pe Shan tun fẹ ọkọ miran sugbọn igbeyawo ọhun ko yọri si rere. Lẹyin eyii ni Shan George fẹ Anthony Nwosisi to jẹ ọkọ rẹ kẹta, sugbọn igbeyawo ọhun ko pẹ to fi tuka bakan naa. | https://www.bbc.com/yoruba/49900829 |
5sports
| Manchester United: Paul Pogba sọ pé òun ti ṣe tán láti padà sórí pápá | Agbabọọlu fun Manchester United, Paul Pogba sọ pe ebi àṣeyọrí lo n pa oun ju bayii lẹyin ti oun padanu ọpọlọpọ ọjọ ninu idije saa yii nitori ifarapa.Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2019, ni Pogba ti gba bọọlu kẹhin, lẹyin to ni ọgbẹ́ ni ẹsẹ̀ ni ibẹrẹ ṣaa.Pogba sọ pe "airikan ṣe kan ti su oun tipẹ", ati pe oun yoo pada sori pápá igbaradi nikete ti aarun coronavirus ba tan nilẹ. Oṣu Kinni ọdun ni wọn ṣe iṣẹ abẹ fún gbajugbaja agbabọọlu naa.Pọgba sọ fun ikọ̀ agbohunsafẹfẹ Manchester United pe oun ko ti i la iru nkan bẹẹ kọja ri lati igba ti oun ti n gba bọọlu jẹun, sugbọn oun gba kadara.O ni: "Mi o ro pe awọn eniyan mọ nkan to ṣẹlẹ si mi gan-an." Pogba ṣalaye pe: "Mo fi ẹsẹ mi ṣẹṣẹ lasiko ti a n gba bọọlu pẹlu Southampton ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ. Eyi jẹ ibẹrẹ ṣaa, mo si mu u mọra fun igba pipẹ; mo n lọ fun igbaradi, mo si tun n gbiyanju lati fi gba bọọlu. Lẹyin ti mo dawọ gbogbo eyi duro ni mo sakiyesi pe egungun mi ti yẹ̀. Ogbontarigi agbabọọlu naa tẹsiwaju pe: "Wọn ba mi fi nkan we e nileewosan. Sugbọn lẹyin asiko diẹ, egungun naa tobi si i, ni mo ba tun pada ṣenu isẹ. Ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Watford ati Newcastle ni mo gba kẹyin ninu oṣu Kejila, ti mo tun fi n ni inira." Ṣugbọn lẹyin isẹ abẹ ti wọn ṣe fun mi, ara mi ti ya. Mo si ti ṣetan lati pada ṣenu isẹ."Ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin ni wọn kọkọ sun idije Premier league siwaju, lẹyin naa ni wọn tun sun un ni ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, nitori ajakalẹ arun coronavirus to n gba ẹbọ lọwọ gbogbo agbaye yiii. | Manchester United: Paul Pogba sọ pé òun ti ṣe tán láti padà sórí pápá Agbabọọlu fun Manchester United, Paul Pogba sọ pe ebi àṣeyọrí lo n pa oun ju bayii lẹyin ti oun padanu ọpọlọpọ ọjọ ninu idije saa yii nitori ifarapa.Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2019, ni Pogba ti gba bọọlu kẹhin, lẹyin to ni ọgbẹ́ ni ẹsẹ̀ ni ibẹrẹ ṣaa.Pogba sọ pe "airikan ṣe kan ti su oun tipẹ", ati pe oun yoo pada sori pápá igbaradi nikete ti aarun coronavirus ba tan nilẹ. Oṣu Kinni ọdun ni wọn ṣe iṣẹ abẹ fún gbajugbaja agbabọọlu naa.Pọgba sọ fun ikọ̀ agbohunsafẹfẹ Manchester United pe oun ko ti i la iru nkan bẹẹ kọja ri lati igba ti oun ti n gba bọọlu jẹun, sugbọn oun gba kadara.O ni: "Mi o ro pe awọn eniyan mọ nkan to ṣẹlẹ si mi gan-an." Pogba ṣalaye pe: "Mo fi ẹsẹ mi ṣẹṣẹ lasiko ti a n gba bọọlu pẹlu Southampton ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ. Eyi jẹ ibẹrẹ ṣaa, mo si mu u mọra fun igba pipẹ; mo n lọ fun igbaradi, mo si tun n gbiyanju lati fi gba bọọlu. Lẹyin ti mo dawọ gbogbo eyi duro ni mo sakiyesi pe egungun mi ti yẹ̀. Ogbontarigi agbabọọlu naa tẹsiwaju pe: "Wọn ba mi fi nkan we e nileewosan. Sugbọn lẹyin asiko diẹ, egungun naa tobi si i, ni mo ba tun pada ṣenu isẹ. Ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Watford ati Newcastle ni mo gba kẹyin ninu oṣu Kejila, ti mo tun fi n ni inira." Ṣugbọn lẹyin isẹ abẹ ti wọn ṣe fun mi, ara mi ti ya. Mo si ti ṣetan lati pada ṣenu isẹ."Ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin ni wọn kọkọ sun idije Premier league siwaju, lẹyin naa ni wọn tun sun un ni ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, nitori ajakalẹ arun coronavirus to n gba ẹbọ lọwọ gbogbo agbaye yiii. | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-52274275 |
5sports
| Samson Siasia: Ẹ rànmí ìrànwọ́ pẹ̀lú N100m láti ṣejọ́ jìbìtì tí FIFA fi kàn mi | Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles, Samson Siasia ti bẹ bẹ iranwo to to ọgọrun un miliọnu naira lati fi ṣe ẹjọ lori ẹsun riba ti ajọ FIFA fi kan an. Loṣu kẹwaa, ọdun 2019 ni ajọ FIFA fẹsun kan Siasia pe o gba lati tẹwọ gba riba lati ṣe eeru ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ kan to ti waye sẹyin. Siasia ni oun ti gbiyanju agbara oun lati wa owo ti yoo fi ṣe ẹjọ naa nile ẹjọ to n ri si awuyewuye to ba jẹyọ nibi ere bọọlu afẹsẹgba lagbaaye. Ṣugbọn awọ ko tii ka oju ilu nitori ọgọrun un miliọnu kii ṣe owo ọmọde owo. Siasia tun ti wa kepe ijọba apapọ atawọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria pe ki wọn ran oun lọwọ pẹlu owo ki oun le yọ orukọ oun ninu ẹsun jibiti ti wọn fi kan oun. Ajọ FIFA fofin de Siasia pe ko gbọdọ ni ohun kankan ṣe mọ pẹlu ere bọọlu, amọ o ni oun ko mọwọ, bẹẹ ni oun ko mẹsẹ lori ọrọ naa. Siasia to wa lara awọn agbabọọlu Naijiria to gba ife ẹyẹ ilẹ Afirika lọdun 1994 lorilẹ-ede Tunisia, sọ pe lori ayelujara loun naa ti gbọ ẹsun ti ajọ FIFA fi kan oun gẹgẹ bi ọpọ ọmọ Naijiria naa ṣe rii. Siasia ni: Mo kan ṣadeedee gba ipe lati ọdọ ọwọ aarẹ ajọ NFF to n dari ere bọọlu ni Naijiria ninu eyi to ti bi mi leere boya mo ti ri lẹta lati ọdọ FIFA, O ni lẹyin naa loun ri lẹta ọhun ninu ẹrọ agbọrọkaye oun ṣugbọn Siasia sọ pe oun ko mọ nnkankan lori ẹsun ti wọn fi kan oun. Yatọ si pe ajọ FIFA fofin de Siasia, ajọ naa tun ni ko san owo itanran bi miliọnu mejidinlogun naira. Igbẹjọ naa yoo waye lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹta ọdun yii niluu Lausanne, lorilẹede Switzerland. | Samson Siasia: Ẹ rànmí ìrànwọ́ pẹ̀lú N100m láti ṣejọ́ jìbìtì tí FIFA fi kàn mi Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles, Samson Siasia ti bẹ bẹ iranwo to to ọgọrun un miliọnu naira lati fi ṣe ẹjọ lori ẹsun riba ti ajọ FIFA fi kan an. Loṣu kẹwaa, ọdun 2019 ni ajọ FIFA fẹsun kan Siasia pe o gba lati tẹwọ gba riba lati ṣe eeru ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ kan to ti waye sẹyin. Siasia ni oun ti gbiyanju agbara oun lati wa owo ti yoo fi ṣe ẹjọ naa nile ẹjọ to n ri si awuyewuye to ba jẹyọ nibi ere bọọlu afẹsẹgba lagbaaye. Ṣugbọn awọ ko tii ka oju ilu nitori ọgọrun un miliọnu kii ṣe owo ọmọde owo. Siasia tun ti wa kepe ijọba apapọ atawọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria pe ki wọn ran oun lọwọ pẹlu owo ki oun le yọ orukọ oun ninu ẹsun jibiti ti wọn fi kan oun. Ajọ FIFA fofin de Siasia pe ko gbọdọ ni ohun kankan ṣe mọ pẹlu ere bọọlu, amọ o ni oun ko mọwọ, bẹẹ ni oun ko mẹsẹ lori ọrọ naa. Siasia to wa lara awọn agbabọọlu Naijiria to gba ife ẹyẹ ilẹ Afirika lọdun 1994 lorilẹ-ede Tunisia, sọ pe lori ayelujara loun naa ti gbọ ẹsun ti ajọ FIFA fi kan oun gẹgẹ bi ọpọ ọmọ Naijiria naa ṣe rii. Siasia ni: Mo kan ṣadeedee gba ipe lati ọdọ ọwọ aarẹ ajọ NFF to n dari ere bọọlu ni Naijiria ninu eyi to ti bi mi leere boya mo ti ri lẹta lati ọdọ FIFA, O ni lẹyin naa loun ri lẹta ọhun ninu ẹrọ agbọrọkaye oun ṣugbọn Siasia sọ pe oun ko mọ nnkankan lori ẹsun ti wọn fi kan oun. Yatọ si pe ajọ FIFA fofin de Siasia, ajọ naa tun ni ko san owo itanran bi miliọnu mejidinlogun naira. Igbẹjọ naa yoo waye lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹta ọdun yii niluu Lausanne, lorilẹede Switzerland. | https://www.bbc.com/yoruba/ere-idaraya-51036888 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.